Discover millions of ebooks, audiobooks, and so much more with a free trial

Only $11.99/month after trial. Cancel anytime.

Àṣìrò Náà: Ìtọ́ni Ẹ̀mi Kan, Àjọ̀nnú Ẹkùn Kan, Pẹ̀lú Ìyá Kan Tí Ó Nkọni Lóminú
Àṣìrò Náà: Ìtọ́ni Ẹ̀mi Kan, Àjọ̀nnú Ẹkùn Kan, Pẹ̀lú Ìyá Kan Tí Ó Nkọni Lóminú
Àṣìrò Náà: Ìtọ́ni Ẹ̀mi Kan, Àjọ̀nnú Ẹkùn Kan, Pẹ̀lú Ìyá Kan Tí Ó Nkọni Lóminú
Ebook69 pages1 hour

Àṣìrò Náà: Ìtọ́ni Ẹ̀mi Kan, Àjọ̀nnú Ẹkùn Kan, Pẹ̀lú Ìyá Kan Tí Ó Nkọni Lóminú

Rating: 0 out of 5 stars

()

Read preview

About this ebook

Megan jẹ́ ọ̀dọ́mọdé alágbára, tí kò lè rí ẹnikẹ́ni láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti lóye àwọn agbára rẹ̀… kò sí alààyè kankan tí ó́́́́́́́́́́́́́́́́́́ yé.
LanguageYoruba
PublisherTektime
Release dateNov 1, 2021
ISBN9788835416654
Àṣìrò Náà: Ìtọ́ni Ẹ̀mi Kan, Àjọ̀nnú Ẹkùn Kan, Pẹ̀lú Ìyá Kan Tí Ó Nkọni Lóminú
Author

Owen Jones

Author Owen Jones, from Barry, South Wales, came to writing novels relatively recently, although he has been writing all his adult life. He has lived and worked in several countries and travelled in many, many more. He speaks, or has spoken, seven languages fluently and is currently learning Thai, since he lived in Thailand with his Thai wife of ten years. "It has never taken me long to learn a language," he says, "but Thai bears no relationship to any other language I have ever studied before." When asked about his style of writing, he said, "I'm a Celt, and we are Romantic. I believe in reincarnation and lots more besides in that vein. Those beliefs, like 'Do unto another...', and 'What goes round comes around', Fate and Karma are central to my life, so they are reflected in my work'. His first novel, 'Daddy's Hobby' from the series 'Behind The Smile: The Story of Lek, a Bar Girl in Pattaya' has become the classic novel on Pattaya bar girls and has been followed by six sequels. However, his largest collection is 'The Megan Series', twenty-three novelettes on the psychic development of a young teenage girl, the subtitle of which, 'A Spirit Guide, A Ghost Tiger and One Scary Mother!' sums them up nicely. After fifteen years of travelling, Owen and his wife are now back in his home town. He sums up his style as: "I write about what I see... or think I see... or dream... and in the end, it's all the same really..."

Read more from Owen Jones

Related to Àṣìrò Náà

Reviews for Àṣìrò Náà

Rating: 0 out of 5 stars
0 ratings

0 ratings0 reviews

What did you think?

Tap to rate

Review must be at least 10 words

    Book preview

    Àṣìrò Náà - Owen Jones

    Àṣìrò Náà

    Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!

    láti ọwọ́

    OWEN JONES

    Ìtumọ̀ láti ọwọ́

    Sola Agboola

    Aṣẹ-lori-ara

    Àṣẹ Àdáni © Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹwàá, Ọdún 2024 Owen Jones

    Àṣìrò Náà

    Àtúntẹ̀ Karún

    Láti ọwọ́ Owen Jones

    A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́

    Megan Publishing Services

    https://meganthemisconception

    Ẹ̀tọ́ Owen Jones láti di mímọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọ ìwé yìí ni a ti tì bọ̀ ọ́ ní ìbámu pẹ̀lú abala 77 àti 78 ti Òfin Àṣẹ Àdáni Iṣẹ́ Ọnà àti Ẹ̀tọ́ ti Ọdún 1988. A ti ti ẹ̀tọ́ ìwà rere ti ònkọ̀wé bọ̀ ọ́.

    Nínú iṣẹ́ àròsọ yìí, àwọn ènìyàn àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ àbájáde àfinúrò ònkọ̀wé tàbí pé a lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àròsọ pọnbélé. Àwọn ibi kan lè wà, ṣùgbọ́n àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ àròsọ.

    Ẹ kàn sí mi ní:

    http://facebook.com/angunjones

    http://twitter.com/owen_author

    http://owencerijones.com

    Ẹ dara pọ̀ mọ́ àtẹ̀jáde wa àtìgbàdégbà fún ìfitónilétí abẹ́lé

    nípa àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ Owen Jones

    nípa títẹ imeeli yín níhin:

    http://meganthemisconception.com

    Àwọn ìwé àkàgbádùn kékeré míràn nínú ọ̀wọ́ kan náà:

    Àwọn Ipele Megan Alágbára

    Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!

    Àṣìrò Náà

    Ìkẹtàlá ti Megan

    Ìrìnàjò Megan Ní Ilé-ìwé

    Àwọn Ìdánwò Megan Ní Ilé-ìwé

    Àwọn Ọmọlẹ́yìn Megan

    Megan Pẹ̀lú Ológbò Náa Tí Ó Sọnù

    Megan àti Obìnrin Olórí Ìlú Náà

    Megan Dojú Kọ Ẹ̀gàn

    Ìbẹ̀wò Baba Àti Ìyá Àgbà Megan

    Ara Baba Megan Ò Dá

    Megan Lọ Fún Ìsinmi

    Megan àti Fọ́léfọ́lé náà

    Megan àti Oníkẹ̀kẹ́ náà

    Megan àti Ìyá Arúgbó náà

    Ọgbà Megan

    Megan Lọ Sí Ọgbà Àwọn Ẹranko

    Megan Lọ Rin Ìrìnàjò Afẹ́

    Megan àti Ìdíje Onjẹ Sísè W. I.

    Megan Wakọ̀ Lọ

    Megan Lọ Wa Ọkọ̀ Ojú Omi

    Megan níbi Àjọ̀dún

    Megan níbi Ọdún Keresimesì

    ÌFISỌRÍ

    Mo fi àtúntẹ̀ yìí sọrí aya mi, Pranom Jones, fún mímú kí ayé mi rọ̀ mí lọ́rùn bí agbára rẹ̀ ti tó, ó nṣiṣẹ́ nlá nípa rẹ̀ àti àwọn òbí mi, Colin àti Marion, fún ìtọ́dàgbà ìyanu tí wọ́n fún èmi àti àwọn arákùnrin mi .

    Karma yóò fi irú rẹ̀ san á fún gbogbo wọn ní òtítọ́.

    ÌJÚBÀ

    Sí aya mi, Pranom fún sùúrù rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ mi Lord David Prosser fún ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ láti ya àwòrán ẹ̀yìn ìwé náà.

    ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ÌṢÍTÍ

    "Máṣe gba ohunkóhun gbọ́ nítorí pé o sá ti gbọ́ ọ,

    Máṣe gba ohunkóhun gbọ nítorí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn sá ti sọ ọ́ tàbí pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fií ṣe àhesọ̀,

    Máṣe gba ohunkóhun gbọ́ nítorí pé o sá ríi tí a kọ ọ́ sínú àwọn ìwé kíkà ti ẹ̀sìn rẹ̀,

    Máṣe gba ounkóhun gbọ́ nítorí àwọn olùkọ́ àti àgbààgbà nìkan,

    Máṣe gba àwọn ìṣẹ̀ṣe gbọ́ nítorí pé nṣe ni a sá bá wọn lọ́wọ́ àwọn ìran tí ó ti kọjá,

    Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìfojúsílẹ̀ àti àgbéyẹ̀wò, tí ohunkóhun bá mú ọgbọ́n wá tí ó sì ṣe àtìlẹ́yìn fún ire àti ànfààní ẹnìkan àti gbogbo ènìyàn, gbà á kí o sì gbé ìgbé ayé tọ̀ ọ́."

    Gautama Buddha

    ------

    Ẹ̀mí Nlá, tí ohùn rẹ̀ wà lórí afẹ́fẹ́, gbọ́ mi. Jẹ́ kí ndàgbà ní okun àti ìmọ̀.

    Jẹ́ kí nrí oòrùn aláwọ̀ pupa àti ti elése àlùkò tí ó nwọ̀ títí láé. Jẹ́ kí ọwọ́ mi ṣe àpọ́nlé àwọn nnkan tí o ti fún mi.

    Kọ́ mi ní àwọn àṣírí tí a fi pamọ́ sí abẹ́ ewé àti òkúta kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí o ti kọ́ àwọn ènìyàn láti ìgbà ìwásẹ̀.

    Jẹ́ kí nlo okun mi, láti máṣe pọ̀ ju arákùnrin mi lọ, ṣùgbọ́n láti bá ọ̀tá mi tí ó ga jùlọ jà – èmi fúnra mi.

    Jẹ́ kí nmáa wá síwájú rẹ ní gbogbo ìgbà pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́ àti ọkàn tí kò ní àbàwọ́n, pé bí ìgbà mi lórí Ilẹ̀ Ayé ti nparẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oòrùn bá wọ̀, kí Ẹ̀mí mi lè padà sí ọ̀dọ̀ rẹ láìsí ìtìjú.

    (Ó dá lórí àdúrà ìbílẹ̀ Sioux kan)

    ÀWỌN ÀKÓÓNÚ

    1 Kò Sí Ṣíṣe, Kò Sí Àìṣe

    2 Ìmọ̀lára Tí Ó Npọ̀ Síi

    3 Olùrànlọ́wọ́ Kékeré Fún Ìyá

    4 Ìmísí

    5 Àwọn Aládúgbò

    6 Àwọn Ọ̀rẹ́ Megan

    Ẹni Tí A Kò Fi Ààyè Gbà

    KÒ SÍ ṢÍṢE, KÒ SÍ ÀÌṢE

    Wọ́n tún ti Megan mọ́ ibi tí wọ́n nkó èédú pamọ́ sí lẹ́ẹ̀kan síi, ó sì ti fẹ́ máa da omi lójú. Ọmọ ọdún méjìlá péré ni, kò sì yé e èrèdí tí ìyá rẹ̀ fi ṣe ohun tí ó burú bẹ́yẹn síi. Ó ti ṣẹlẹ̀ nígbà mélòó kan tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n bóyá baba rẹ̀ kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀. Kò tíì sọ fún baba rẹ̀ rí, ó sì dá a lójú pé ìyá òun kò tíì níí sọ nnkan kan bákan náà.

    Àdéhùn ìmọ̀sínú kan wà láárín òun àti ìyá rẹ̀ pé kí àwọn méjèèjì máṣe já ara wọn kulẹ̀, ṣùgbọ́n òun tún nìyí níhín, tí ó njókòó sínú ibi tí wọ́n nkó èédú pamọ́ sí, nínú ìdọ̀tí àti ekuru pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá búburú tí a ò lè sọ tí ó nfi ojú síi lára.

    Òun ò mọ̀. Òkùnkùn ṣú dudu, ó sì lo gbogbo agbára rẹ̀ láti máṣe sọkún kí ó sì bẹ ìyá rẹ̀ láti tú òun sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ti gbìyànjú ìyẹn ní àwọn ìgbà míràn, ìyá rẹ̀ sì ti sọ pé kí ó ṣe àwọn nnkan tí ó nira gẹ́gẹ́ bí èrèdí tí òun lè fi dá a sílẹ̀. Àwọn ohun tí ó mọ̀ pé kò lè ṣeéṣe, bí ó ti wù kí ó gbìyànjú tó.

    Nígbà míràn, ó máa ndàbí ẹni pé òun nìkan ni ó ka àdéhùn náà sí.

    Omijé tún bẹ̀rẹ̀ síí fúnra rẹ̀ ṣàn lọ sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀, tí ó ngbẹ́ ipa odò àìrí la ekuru ojú rẹ̀ kọjá, tí ó nṣan ekuru èédú lọ sí ìsàlẹ̀ aṣo ẹgbẹ́jọdá ilè-ìwé rẹ̀. Ó ti pọ̀jù, ó dìídì pọ̀. Báwo ni ẹnìkan tí wọ́n jọ gbọ́ ara wọn yé dáradára tó bẹ́ẹ̀, ti lè hùwà tí ó burú bẹ́yẹn sí ọmọbìnrin rẹ̀ kanṣoṣo?

    Megan kò mọ ìgbà tí ó tọ sókè bí

    Enjoying the preview?
    Page 1 of 1