Discover millions of ebooks, audiobooks, and so much more with a free trial

Only $11.99/month after trial. Cancel anytime.

Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!
Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!
Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!
Ebook53 pages49 minutes

Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!

Rating: 0 out of 5 stars

()

Read preview

About this ebook

Ìjádelọ ọlọ́dọọdún ilé-ìwé Megan mú òun àti àwọn ojúgbà rẹ̀ lọ sí àpapọ̀ sí àwọn àṣàpọ̀ ihò, tí àwọn ẹ̀yà tí ó wà ṣáájú ìtàn kíkọ fi nṣe ibùgbé. Ó dá Megan lójú pé òun nní ìmọ̀ síi nípa ohun tí ó dìídì ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí ó pẹ́ tó bẹ́yẹn nípa lílo àwọn agbára àìmọ̀ rẹ̀, ju ohun tí àwọn afinimọ̀nà tí wọ́n gbà fún wọn lè sọ fún wọn.
LanguageYoruba
PublisherTektime
Release dateFeb 13, 2021
ISBN9788835418986
Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan: Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!
Author

Owen Jones

Author Owen Jones, from Barry, South Wales, came to writing novels relatively recently, although he has been writing all his adult life. He has lived and worked in several countries and travelled in many, many more. He speaks, or has spoken, seven languages fluently and is currently learning Thai, since he lived in Thailand with his Thai wife of ten years. "It has never taken me long to learn a language," he says, "but Thai bears no relationship to any other language I have ever studied before." When asked about his style of writing, he said, "I'm a Celt, and we are Romantic. I believe in reincarnation and lots more besides in that vein. Those beliefs, like 'Do unto another...', and 'What goes round comes around', Fate and Karma are central to my life, so they are reflected in my work'. His first novel, 'Daddy's Hobby' from the series 'Behind The Smile: The Story of Lek, a Bar Girl in Pattaya' has become the classic novel on Pattaya bar girls and has been followed by six sequels. However, his largest collection is 'The Megan Series', twenty-three novelettes on the psychic development of a young teenage girl, the subtitle of which, 'A Spirit Guide, A Ghost Tiger and One Scary Mother!' sums them up nicely. After fifteen years of travelling, Owen and his wife are now back in his home town. He sums up his style as: "I write about what I see... or think I see... or dream... and in the end, it's all the same really..."

Read more from Owen Jones

Related to Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan

Reviews for Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan

Rating: 0 out of 5 stars
0 ratings

0 ratings0 reviews

What did you think?

Tap to rate

Review must be at least 10 words

    Book preview

    Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan - Owen Jones

    ÌFISỌRÍ

    Mo fi àtẹ̀jáde yìí sọrí arákùnrin mi Gareth, ẹni tí ó ran èmi àti ìdílé mi ilẹ̀ Thailand lọ́wọ́ ju bí ó ti mọ̀ ní ọdún 2013 lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́ kan tí mo fi inú tán gbìyànjú gidigidi láti pa wá lára. Karma yóò san á padà fún olúkúlùkù bí ó ti tọ́.

    Ẹ kàn sí mi ní:

    http://facebook.com/angunjones

    http://twitter.com/owen_author

    owen@behind-the-smile.org

    http://owencerijones.com

    Ẹ dara pọ̀ mọ́ àtẹ̀jáde wa àtìgbàdégbà fún ìfitónilétí abẹ́lé nípa àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ Owen Jones nípa títẹ adirẹsì imeeli yín níhin:

    http://meganthemisconception.com

    Àwọn ìwé àkàgbádùn kéékèèké míràn ní ipele kan náà:

    Àwọn Ipele Ti Megan

    Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!

    Àṣìrò Náà

    Ìkẹtàlá ti Megan

    Ìrìnàjò Ilé-ìwé Megan

    Àwọn Ìdánwò Megan Ní Ilé-ìwé

    Àwọn Ọmọlẹ́yìn Megan

    Megan Pẹ̀lú Ológbò Náa Tí Ó Sọnù

    Megan àti Obìnrin Olórí Ìlú Náà

    Megan Dojú Kọ Ẹ̀gàn

    Ìbẹ̀wò Baba Àgbà Àti Ìyá Àgbà Megan

    Ara Baba Megan Ò Dá

    Megan Lọ Fún Ìsinmi

    Megan àti Fọ́léfọ́lé náà

    Megan àti Oníkẹ̀kẹ́ náà

    Megan àti Ìyá Arúgbó náà

    Ọgbà Megan

    Megan Lọ Sí Ọgbà Àwọn Ẹranko

    Megan Rin Ìrìn Afẹ́ Lọ

    Megan àti Ìdíje Onjẹ Sísè W. I.

    Megan Wakọ̀ Lo

    Megan Lọ Wa Ọkọ̀ Ojú Omi

    Megan níbi Àjọ̀dún

    Megan níbi Ọdún Keresimesì

    ÀWỌN ÀKÓÓNÚ

    Ìmọyì

    1 Ìrìnàjò Ilé-ìwé Náà

    2 Ẹ̀kọ́ Kan Nípa Ìtara

    3 Ìdìbò Náà

    4 Àwọn Ihò Tí Ó Ti Wà Kí Wọ́n Tó Kọ Ìtàn

    5 Èrò Inú Ọkùnrin Inú Ihò Náà

    ÌMỌYÌ

    Sí aya mi, Neem fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn rẹ̀ lórí àwọn páálí ẹ̀yìn ìwé ti ipele yìí àti sí Rachel Maduro, tí ó ya gbogbo àwòrán wọn ní ọ̀nà tí ó ṣe rẹ́gí tó bẹ́ẹ̀, tí ó ngbá gbogbo bí nnkan ṣe rí mú ní àkókò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú àlàyé tí ó kéré tó bẹ́ẹ̀ láti tẹ̀ síwájú. Mi ò mọ̀ bí ó ti nṣe é.

    1 ÌRÌNÀJÒ ILÉ-ÌWÉ NÁÀ

    Bí oṣù kẹrin ọdún ti nwá sópin, olórí àwọn olùkọ́ nì klaasì kéde fún klaasì kọ̀ọ̀kan, pé ilé-̀ìwé náà yóò ṣètò ìrìnàjò fún àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n tí àwọn òbí wọn yóò sì gbà láàyè láti lọ. Èyí kìí wáyé ní ọdọọdún, nítorí pé kìí ṣe àwọn aláṣẹ ilé-ìwé ni ó nnáwó lórí irú ìrìnàjò yẹn. Àwọn ọmọ ilé-ìwé, àwọn òbí wọn àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ìwé ni ó máa nwá owó náà. Wọ́n sá sábà máa ngbìyànjú láti lọ sí ibi kan ní ọdún méjì nínú mẹ́ta, bí kò tilẹ̀ jìnnà púpọ̀. Fún àwọn kan lára àwọn ọmọ náà, àkókò ìrìnàjò afẹ́ kanṣoṣo tí wọ́n nní nìyẹn.

    Aya Henshaw, tíí ṣe olórí àwọn olùkọ́ nì klaasì Megan ṣe ìkéde kan lẹ́yìn ìsìn àti ìforúkọsílẹ̀ òwúrọ̀ pé:

    Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Hughes, ọ̀gá ilé-ìwé ti sọ ṣáájú ní òwúrọ̀ yìí, Ẹgbẹ́ Òbí àti Olùkọ́ ti kó owó tí ó tó jọ láti fi ààyè gbà wá láti tún kó yín, ẹ̀yin tí wọn ò tíì tì mọ́lé ní oṣù méjìlá sẹ́yìn, lọ fún ọjọ́ náà ní ọdún yìí.

    "Ọ̀gbẹ́ni Hughes ti dábàá ojúkò mẹ́ta fún ìrìnàjò náà, wọ́n sì ti sọ pé kí nfi wọ́n hàn yín báyìí. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí wá àlòkù ìwé yín kí ẹ sì kọ wọ́n sílẹ̀  nísisìyí, ẹ jọ̀wọ́:

    Nọmbà Kínní: Ibi kan tí wọ́n ti jagun ní ìgbà àtijọ́.

    Nọmbà Kejì: Ibi ìjọ́sìn ìgbàanì kan.

    Nọmbà Kẹta: Ibi kan tí ó wuni tí ó ti wà kí wọ́n tó máa kọ ìtàn."

    Ọ̀gbẹ́ni Hughes yóò fẹ́ kí ẹ ronú nípa ibi tí ẹ ó fẹ́ láti ṣe ìbẹ̀wò sí, kí ẹ sì kúkú bá àwọn òbí yín sọ ọ́. Ẹ ó ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí da Ọjọ́ Ajé tí ó nbọ̀, nígbà tí ìjíròrò ránpẹ́ yóò wáyé lẹ́yìn ìsìn òwúrọ̀ tí ẹ ó sì lè dìbò.

    "Nígbà tí a ò níí máa sọ ibi tí a nlọ gangan nínú àwọn ọ̀nà mẹ́ta yìí, kí a lè fún ìrìnàjò ilé-ìwé náà ní àpọ́nlé díẹ̀, ẹ lè fi dá àwọn òbí yín lójú pé orílẹ̀-èdè yìí ni a ó ti dúró – kí á sọ òtítọ́ a ò níí kọjá agbègbè yìí. A ò gba owó tí ó pọ̀ tó bẹ́yẹn, ṣùgbọ́n èyí

    Enjoying the preview?
    Page 1 of 1