Discover millions of ebooks, audiobooks, and so much more with a free trial

Only $11.99/month after trial. Cancel anytime.

Òkú Ààrin-Gbùngbùn: Kì Í Se Gbogbo Awọn Tó Pa Ara Wọn Ni Ẹlẹsìn!
Òkú Ààrin-Gbùngbùn: Kì Í Se Gbogbo Awọn Tó Pa Ara Wọn Ni Ẹlẹsìn!
Òkú Ààrin-Gbùngbùn: Kì Í Se Gbogbo Awọn Tó Pa Ara Wọn Ni Ẹlẹsìn!
Ebook324 pages4 hours

Òkú Ààrin-Gbùngbùn: Kì Í Se Gbogbo Awọn Tó Pa Ara Wọn Ni Ẹlẹsìn!

Rating: 5 out of 5 stars

5/5

()

Read preview

About this ebook

Àdó ólóró buburu kan bú jáde ni ile ìtàjà nla kan ni Baghdad, ti o pa pupọ awọn olùrajà ati osisẹ, ti ọpọlọpọ si yarọ. Laipẹ, awọn ẹgbẹ bọmbà olupara-ẹni tuntun di awọn ẹniti awọn ọlọpa meje lagbàáyé nwákiri nitoripe wọn ti di ẹrùjẹjẹ fún ara ilu, ti kò ni i se pẹlu ẹsìn tabi òsèlú. Wọn pe awọn akọsẹmọsẹ ẹrọ ayárabiàsá ti ijọba Ṣháínà ati SAS ti Gẹẹsi lati sèrànwọ, sugbọn njẹ wọn yio le sàwári okùnfà bọmbù tó nsẹlẹ lemọlemọ ki ó tó di wipé ọwọ ara ilu kò ni ká wọn mọ?
LanguageYoruba
PublisherTektime
Release dateJan 1, 2024
ISBN9788835441649
Òkú Ààrin-Gbùngbùn: Kì Í Se Gbogbo Awọn Tó Pa Ara Wọn Ni Ẹlẹsìn!
Author

Owen Jones

Author Owen Jones, from Barry, South Wales, came to writing novels relatively recently, although he has been writing all his adult life. He has lived and worked in several countries and travelled in many, many more. He speaks, or has spoken, seven languages fluently and is currently learning Thai, since he lived in Thailand with his Thai wife of ten years. "It has never taken me long to learn a language," he says, "but Thai bears no relationship to any other language I have ever studied before." When asked about his style of writing, he said, "I'm a Celt, and we are Romantic. I believe in reincarnation and lots more besides in that vein. Those beliefs, like 'Do unto another...', and 'What goes round comes around', Fate and Karma are central to my life, so they are reflected in my work'. His first novel, 'Daddy's Hobby' from the series 'Behind The Smile: The Story of Lek, a Bar Girl in Pattaya' has become the classic novel on Pattaya bar girls and has been followed by six sequels. However, his largest collection is 'The Megan Series', twenty-three novelettes on the psychic development of a young teenage girl, the subtitle of which, 'A Spirit Guide, A Ghost Tiger and One Scary Mother!' sums them up nicely. After fifteen years of travelling, Owen and his wife are now back in his home town. He sums up his style as: "I write about what I see... or think I see... or dream... and in the end, it's all the same really..."

Read more from Owen Jones

Related to Òkú Ààrin-Gbùngbùn

Reviews for Òkú Ààrin-Gbùngbùn

Rating: 5 out of 5 stars
5/5

1 rating0 reviews

What did you think?

Tap to rate

Review must be at least 10 words

    Book preview

    Òkú Ààrin-Gbùngbùn - Owen Jones

    Aṣẹ-lori-ara

    Àṣẹkíkọ © 2024 Owen Jones

    Òkú Ààrin Gbùngbùn 2

    Kódà nǹkan tí kò dára le dára nígbàmíràn!

    Lati ọwọ Owen Jones

    Iwé Titẹ nipasẹ

    Megan Publishing Services

    https://meganthemisconception.com

    Copyright © 2024 Owen Jones

    Ẹtọ Owen Jones lati jẹ idánimọ gẹgẹbi ònkọwé  yi ni a fidi rẹ múlẹ ninu Ipin 77 ati 78 ti Òfin Copyright Designs and Patents 1988. Ẹtọ ònkọwé náà ni a ti fidi rẹ múlẹ.

    Ninu isẹ àròsọ yi, awọn eniyan ati isẹlẹ jẹ yálà iwoye ti ònkọwé tabi wọn lò wọn gẹgẹbi àròsọ.  Awọn ibi kan le wà, sugbọn aròsọ patapata ni awọn isẹlẹ náà..

    Gbogbo awọn ẹtọ wa ni ipamọ!

    Yi Series

    Òkú Ààrin Gbùngbùn

    Kìí Se Gbogbo Ẹnitó Pa’ra Rẹ Ni Ó Jẹ Ẹlẹsìn

    -

    Òkú Ààrin Gbùngbùn 2

    Kódà nǹkan tí kò dára le dára nígbàmíràn!

    Kàn si mi ni:

    http://facebook.com/angunjones

    http://twitter.com/lekwilliams

    http://owencerijones.com

    Darapọ mọ lẹtairòhin wa fún iwifún-ni abẹ’lé

    lóri awọn iwé Owen Jones

    nipa sise àbẹwò sí

    https://meganthemisconception.com

    YIYÀSỌTỌ

    Mo ya ẹdà iwé yi sọtọ fun iyawo mi, Pranom Jones, ti ó fi ayé rọrùn fún mi niwọn tí ó le se – ó se isẹ takuntakun le lori.

    Kama yio san fún olúkúlùkù.

    MÍMỌ RÍRÌ

    Mo dupẹ lọwọ arakunrin mi, Rhys Jones, fún irànlọwọ, imọràn ati awọn àbá rẹ, ati ònkọwé ọrẹ mi, , Lord David Prosser fún awọn èrò rẹ lori ibora na ati ìgbaniníyànjú rẹ.

    ÀWỌN ỌRỌ IMÍSÍ TI ÀWỌN ẸLÒMIRÀN

    Máse gba ohunkókun gbọ nitoripé o gbọ ọ,

    Máse gba ohunkókun gbọ nitoripé wọn sọ ọ, ọpọlọpọ awọn eniyan si sọ di ọrọ àhesọ,

    Máse gba ohunkókun gbọ nitoripé ó jẹ àkọsilẹ ninu awọn iwe ẹsìn rẹ,

    Máse gba ohunkókun gbọ nitoripé awọn olùkọ ati alàgba fi asẹ si i,

    Máse gba awọn àsà isànbáyé gbọ nitoripe wọn jẹ atọwọdọwọ lati irandiran,

    Sugbọn lẹhin iwòye ati itúpalẹ, ti ohunkóhun bá fa ọgbọn yọ ti o si se anfaani fun gbogbo eniyan, gbà á ki o si mu u lò.

    Gautama Buddha

    ––

    Ẹmi Nlá, ẹniti ohùn rẹ wà ninu afẹfẹ, gbọ mi. Jẹki ndàgbà ni agbára ati imọ.

    Jẹki n má a wo iwọ-oòrùn pupa ati pọpù.  Jẹki ọwọ mi bọwọ fún awọn ohún ti o ti fún mi.

    Kọ mi ni awọn asiri ti wọn wà ni ipamọ lábẹ ewé kọọkan ati òkúta, gẹgẹbi o ti kọ awọn eniyan lati ayébayé.

    Jẹki nlo agbára mi, ki i se lati tóbi ju arakunrin mi lọ, sugbọn lati bá ọtá mi to lagbara jùlọ jà – èmi tikalara mi.

    Jẹki nwa siwaju rẹ nigbagbogbo pẹlu ọwọ mimọ ati ọkan sísí, pé bi ọjọ Ayé mi ti nlọ bi iwọ-oòrùn, Ẹmi mi yio padà sọdọ rẹ laisi itijú.

    (Ó duro lori adura ibilẹ Sioux)

    ÀWỌN ÀKÓÓNÚ

    Mimọ Rírì

    1 Scheherazade’s, Baghdad

    2 Birmingham, Alabama

    3 Peckham, London

    4 Idojúkọ Genaro Àkọkọ

    5 Fun Igbà Diẹ

    6 Ole Jijà ọkọ Ojú-Irin, Essen

    7 Marseille

    8 Ayélujára Náà

    9 Slaintie, Belfast

    10 Ogún-Ibí Peteru

    11 Thailand

    12 Olójufẹ Ti A Kọ Silẹ, New York

    13 Awọn Iwádii Ọlọpa

    14 Ìkọlù Awọn Ṣẹrùbani ni London

    15 Ọkunrin Giga ti Boliches

    16 Dééf Aṣiwèrè, St. David’s

    17 Ọga Marina, Barry

    18 Ọrọ Asọgbẹyin

    Nipa Ònkọwé Náà

    Tj A Kò Fi Ààyè Gbà – Orí Kini

    1 SCHEHERAZADE’S BAGHDAD

    Ẹrù ba Tony, sugbọn ó mọ wipé nkan ti ó kù fún òun lati yàn niyẹn. Ó si tún mọ wipe ni isẹjú diẹ si, ọgọọgọrun awọn èniyan ni ẹrù yio bà lọpọlọpọ ju bayi lọ. 

    Ó mọ ilànà tirẹ̀, o si ti kọ wọn sori patapata.  Kódà ó le ri aago nla lẹgbẹ ògiri ti yio fi máa sisẹ.  Ó wo bi ọwọ aago naa ti nyi lọ sisàlẹ, ó sì mí kanlẹ̀ lati fi ọkàn ara rẹ̀ balẹ̀, ooru kò mú lọjọ naa, sugbon ó nlàágùn gidigidi, nitorina ó mu asọ inujú pélébé lati inu ẹwù àyà rẹ̀, ó duro niwaju dígí kan lati fi ba ojú rẹ̀. 

    Ó bẹrẹ si farabalẹ, Félíọmù naa nsisẹ.  Kò rò wipe yio rọrùn bayi.  Ó sì ni ọgọrun mita si i lati rin ati isẹjú mẹẹdogún lati rìn ín.  Ó nfẹsẹ̀ gbálẹ̀, ó si nwo awọn asọ na lójú ọnà, pẹlú ìyàlẹnu pé, kò si ọkankan ti yio jámọ nkankan láipẹ; ó si yàá lẹnu boya yio se bẹẹ.  Awọn sẹẹti, sòkòtò gbọọrọ, awọn súútù, awọn ohun olóòrun didun awọn okunrin…ó fọwọkan diẹ lára wọn, bi igbà ti eniyan bá fọwọkan òdòdó kan, lẹhinna ó lọ soke si ibi asọ awọn obirin láarin ọnà tó lọ si ẹka ibi ohun sise ara l’ẹsọ.  Ó mọ ọnà naa; ó ti rin ibẹ ni ọpọlọpọ igbà. 

    Ó ku isẹjú meji lati lọ, àya rẹ̀ já.  Duro fun àáyá isẹjú diẹ si, máse ti awọn kábinẹti àfihàn ọjà, ni wọn sọ fun.  Kodà wọn ti fun ni ààlà ti kò gbọdọ kọja; kiyesi, ó si wà ni mita kan niwaju rẹ̀.  Ó duro ni àayè rẹ̀, nibiti awọn abala meji àarin ọnà kápẹẹti ti papọ mọra, ó si se bi ẹniti o nka ipolówó ọjà kan. 

    Ó ku àáyá isẹjú mẹẹdógún lati lọ.  Ó wò yika ara rẹ, oju rẹ bàjẹ. 

    Àáyá isẹju mẹwa, oju òun ati òntajà kan pàdé ó si bẹrẹ si rin wá sọdọ rẹ̀, ó gbiyanju lati jẹki ó má a bá tiẹ̀ lọ. 

    Ni àáyá isẹju marun, arabirin naa ti bẹ̀rẹ̀ si sọrọ si, sugbọn kò fetisilẹ.  Mẹrin, mẹta, meji, ẹyọkan…

    Òfo. 

    Bùmù! 

    Arabirin naa kò gbọ ki okunrin na wipe, má binu, à mọ sá, àti arabirin ati Tony, àwọn mejeji  di èrò ọrun. 

    Lẹhin ìró ariwo tó dinileti, idakẹrọrọ wà fun ọpọlọpọ àáyá isẹju, ki igbe tó bẹ̀rẹ̀.  Awọn eniyan nké, wọn nkigbe, wọn si nsá àsálà fun ẹ̀mi wọn, ìyẹn awọn tó le sáré.  Awọn eniyan pọ ti wọn wà nilẹ ati èéfin latibi ọpọlọpọ ina. 

    Èèfin ati igbe oró ati òórùn ati ẹ̀rù ati Sẹmtẹksi ati àfọnká ẹ̀jẹ̀ Tony ati arabirin òntajà ni gbogbo òrùlé ati awọn asọ ati awọn onrajà.  Itaniji ilé itajà naa bẹ̀rẹ̀, ati ẹ̀rọ ifọnmiká lẹhin àáyá isẹju tó tẹ̀le. 

    Awọn okunrin ninu asọ dúdú sáre wọlé lati ibi àtẹgùn pajáwiri, sugbọn wọn wá lati ran ara wọn lọwọ ni, kì í se lati sèrànwọ fun awọn tó farapa, wọn si gbé ibọn, ki i se àpò egbogi, ki i se wipe wọn ni ìdojúkọ.

    Ni ọjọ keji, àwọn iwé iroyin sọ wipe, ó kéré tán ọgbọn eniyan ni wọn pa, ti àádọjọ si farapa ninu àdó olóró ti o bú jade ni ile itaja laarin gbùngbùn Baghdad. 

    Kò si ohun miran lati kà ninu awọn iwe iroyin tabi lati ri lori ẹrọ móhùn-máwòrán,  sugbọn awọn ile-isẹ ìṣèdúró nsá sókèsódò nitori idigun-jalè lati ibi itaja naa, bẹẹna si ni awọn ile-isẹ ọtẹlẹ̀múyẹ. 

    Miliọnu mẹwa ati ààbọ dọla iye awọn ẹrù ni wọn ji lọ latari irukerudo naa, kò si si àpẹẹrẹ lati mu awọn ọdaràn na.  Wọn gbé Tony lori CCTV, sugbọn oun naa ti kú.  Wọn ri wipe iyẹn naa sẹlẹ, sugbọn kamẹra naa kò sisẹ.  Wọn ka awọn òfò yi kun isẹ ‘awọn jàndukú, bóyá awọn agbófinró naa wà lara wọn, ati awọn òsisẹ ti wọn nsisẹ imọtótó‘ ti wọn si fi silẹ báyẹn. 

    Kì í se ohun tuntun lati gbọ wipé awọn osisẹ tó nsọ ẹsọ ati awọn olùtọjú ilé-isẹ naa máa nji awọn ohun iyebiye ti wọn ba rí nigbati wọn bá nsisẹ àjàmbàkù wọn.  Ó jẹ àjẹmọnú kò si sí ẹni ti ó bikità bi wọn ba ji ẹrù ile-isẹ Ìṣèdúró Ọlọlá Western kó lọ, atipé bi gbólóhùn kan bá wà ti ó lòdi si isẹlẹ ogun ati sisẹrùbani, latari èyi, awọn olówó kan ni yio san’gbèsè rẹ, eyi kò si kan ẹnikankan.

    Òkú, àwọn tó di aláàbọ ara, ati awọn mọlẹbi wọn nikan ni àwọn èniyàn sèdárò fún, ki i se awọn tó ni ile itaja.

    Àwọn ohun meji to hàn gbangba nipa iparaẹni ile itaja Scheherazade naa ni kàyéfì tí ó jẹ, ati idààmu ti ó kó bá awọn ara ilu agbegbe naa pẹlu asiko ti wọn lò lati palẹ ibi isẹlẹ naa mọ, lati jẹki ó tún wà láìléwu ati sisi ile itaja naa lẹẹkan si.

    Iparun ti ó mú bá awọn onibara ati awọn òsisẹ naa ga lọpọlọpọ, sugbọn ile itaja naa kò bajẹ pupọ, nitoripe wọn sẹsẹ fi awọn okuta pẹlẹbẹ mábù dí awọn ògiri ẹka ohun isara lọsọ, wọn si duro sinsin ni akoko ìró ẹtù náà, eyi ti wọn se lati pàniyàn ati lati sọni di alaabọ ara, sugbọn ki i se lati ba ile jẹ.

    Ọta onibùú mẹfa ti ó yi ẹtù naa ka wúwo tóbẹẹ tó jẹ wipe ó tó lati paniyàn, kó si fọn gilasi tó le ká, sugbọn ki i se lati wó ogiri tabi ki ó já awọn òrùlé.  Sibẹsibẹ, ki i se ọpọlọpọ eniyan ni ó mọ iyẹn, bẹẹni Tony náà kò mọ.

    Iwadi isẹlẹ naa bẹrẹ ni kiakia lọsan ọjọ yẹn nigbati awọn olusọ ile itaja naa kó awọn igbàsilẹ kámẹràa wọn fún awọn ọlọpa ki wọn ba le bẹrẹ si tọpasẹ awọn tó wà nidi isẹlẹ naa.

    Awọn kámẹrà olusọna wà lori ‘gilóbù didán’, mẹfa lẹgbẹ kọọkan, ti wọn so rọ lati ibi awọn òrùlé naa ni ayiká ile itaja naa tó jẹ wipé kámẹrà wà ni gbogbo àyika ile itaja naa.  Kì í se gbogbo kámẹrà naa ni wọn nsisẹ ni gbogbo igbà, sugbọn ẹyọkọọkan á sisẹ fún àáyá-isẹjú mẹwa ki lẹnsì kámẹrà tó tẹle tó bẹrẹ si sisẹ. Wọn se àgbekalẹ ati titan awọn gilóbù naa, tó jẹ wipé ó fẹrẹ jẹ wipé gbogbo àyiká ile itaja naa ni ó wà lábẹ sísọ ni gbogbo igbà, lati orisirisi igun ati orisirisi ibùdó ifojusùn.

    Awọn Ọlọpa Ijọba Apapọ wo igbàsilẹ isẹlẹ naa latẹhin titi dé ibiti ẹtù naa ti gbina, ki wọn le ni awòrán ẹniti ó sisẹ naa, ki wọn si sàwári bi ó se wọlé sínú ile itaja naa.  Nigbati wọn ti ri bi ó se wọlé itaja naa, ó rọrùn lati tọpasẹ awọn ìrìn rẹ.  Gbogbo awọn ọgá ló gba wipe, pẹlu oju inu, ó rọrùn lati ri wipé ó ni nkankan lati fi pamọ nipa bi ó se nse, ti ki i bá se nipa asọ rẹ.  Kò wò bi ẹniti ó di ihamọra.

    Awọn ọgá mẹfa ni wọn wo isẹlẹ naa ni oju awò titobi ati kékeré, nitori awò nlá gbé àwòrán nla jádé, bi o tilẹ jẹ wipé ó se é se lati se àtúnse si iselana ẹnikọọkan nipa sọftiweà ti a se fún èyí.

    Wọn wo Tony, botilẹjẹ wipé wọn kò mọ orúkọ rẹ, fún bii ogún isẹjú ti o wà ni ile itaja naa, wọn wo igbàsilẹ isẹlẹ naa ni yiyara ati ni jẹẹjẹ.

    Ni ọpọlọpọ igbà.

    Wọn wòó, wọn si fi gbogbo òru wòó fiimù náà, léraléra lẹẹkan si, bi awọn onimọ idanimọ iwa ọdaràn ati awọn ọlọpa ati awọn ọgágun ti nse àyẹwò isẹlẹ búburú naa.

    Ni idáji, lẹhin wákàtí mẹrinlá, wọn niláti dúró, wọn si fi tipátipá lọ silé lati simi. Awọn osisẹ alẹ gba’sẹ, sugbọn fún afikun akoko titi di igbàti awọn osisẹ ọsán yio padà wá lẹhin wákàtí marún ti wọn. Wọn wo isẹlẹ naa leralera wọn si kọ awọn nkan silẹ, ti wọn le salábapin pẹlu ara wọn.

    Ohun kan ti gbogbo awọn osisẹ alẹ ati ọsàn f’ohùn si ni wipé, dájúdájú bọmbà naa gbọn-rìrì, ọgá àgbà awọn osisẹ alẹ kọ akọsilẹ ti ó ni àfikún awọn abala fiimù naa ninu idánilẹkọ fidiò fún awọn osisẹ olusọ lori bi wọn se le sèdánimọ awọn eniyàn ti wọn bá nhuwà ifura.  Sugbọn, wọn kò ni ojútùú fún awọn yókù.

    Nigbati awọn osisẹ ọsán gba’sẹ, wọn nmu kọfi, wọn si tún nwo isẹlẹ naa ni iyàrá jẹẹjẹ.

    Saà, ẹ dúró nibẹyẹn! ẹ yi sẹhin fún isẹjú àáyá diẹ, ẹ jọwọ, bayi, ni iselana kọọkan ki ẹ si setán lati dadúro nigbati mo ba sọ bẹẹ, ni arabirin ọlọpa Ijọba Apapọ kan sọ. "Ó dàbi pé mo ri nkankan … S’ó o ri báyẹn? Ọgá naa nu oju rẹ, ó si wò ó ! ! Awọ biráùn wà lori asọ ìnujú rẹ! Ó nilati jẹ wipé eruku pọ lánàá, tabi … Ó dabi wipe arakunrin wa nwọ asọ òfegè. Àwa, tabi ó kérétán Èmi, ti lerò wipé Ààrin Gbùngbùn Ìhà-Ìlà Oòrùn ló ti wá, sugbọn bayi kò dá mi lójú.  Wò ó, iwájú ori rẹ funfun sí i bayi … pẹlú irún diẹ. Ẹ lọ sẹhin ki a tún wòó lẹẹkan si sà, ti ẹ bá fẹ.  Se ẹ ri nkan ti mo sọ?

    Ó le jẹ Òyinbó bí?

    Wo abala isẹlẹ yi lẹẹkan si léraléra.

    Suzette, ó se é se ki o ni nkankan nibẹyẹn, ni ọgá adari ọlọpa Ijọba Àpapọ Kapteni Ali Allawi sọ, kini ẹyin èèyàn rò?"

    Ọpọlọpọ gbà, bẹẹbẹẹ.

    Nitorina, bọmbà wa le máse jẹ Lárúbáwá tabi kó ó wá lati agbègbè wọnyi rárá.  Mo sàkiyesi wipe kò pariwo ‘Allahu Akbar!’ nigbati ó yin ẹtù naa.

    Njẹ o le jẹki a ri ojú rẹ daadaa?

    Arabirin onimọ ẹrọ IT naa fọwọkan awọn kókó kan, ó si sún awọn siláídà díẹ lati jẹki awòrán naa tobi si i.

    Sà.

    Jùú sóke lori awọn awò mejeeji, ki o tó awọn ẹda mejila, jọọ.

    Awọn ọga naa sayẹwò awọn awò naa ati awọn atẹjade finifini.

    Njẹ o le se àyidáyidà awòrán yi , Lẹftẹnanti? Gbiyànjú lati yọ awọn ìpénpéju yẹn kuro ati irun imú, ki o si jẹki àwọ rẹ mọ si, pàápàá julọ ni àyiká awọn ojú. Ó dáa báyẹn, jẹkó se rẹsirẹsi diẹ, ariwa Yúrópù. Bẹẹni.

    Ó dáá. Bayi fun ni irun alawọ rẹsúrẹsú dipò dudu, bẹẹni, òun niyẹn. Ó le jẹ ara Yúropù tabi ki iran rẹ wá lati Yúrópù, sugbọn ọta naa jin, ó jin púpọ.  Njẹ Isẹlẹ Wahala ti sẹlẹ rí si i, ti a le lò fún Kaadi ìdánimọ?

    Rárá sà, kò ti i sí. Kò sí ọkankan ti mo mọ. Ìró naa yọ pọdi awọn kámẹrà ati mọnàmọná kuro nibi awọn awòrán tó wà nita lara awọn kámẹrà nitosi, nitorina a kò mọ ibiti eyikeyi rẹ fò lọ, sà."

    Ó dáa, pe ẹnikan lori ẹrọ ibánisọrọ ki ó sàyẹwò.

    Saà! Màá se bẹẹ lẹsẹkẹsẹ, saà! Nigbati mo pè ni ìṣẹjú mẹẹdógún sẹyin, wọn ni ipàniyàn púpọ wà, tó jẹ wipé kò sẹni tó le dá ẹnikẹni mọ ni nkan bi ogún mità  si ibi ti bọmbà náà wà. Wọn sọ pé ó nira, ati wipé kò se é se lati se ìdánimọ awọn àsopọ DNA lẹgbẹ ògiri ati òrùlé nitori àwọn ìbàjẹ èéfín. Ìbàjẹ, saà.

    Ó dáa, Lẹftẹnanti. Máa sọ wọn kó o si jẹki nmọ, ni kété ti nkankan bá sẹlẹ - lọsán tabi lálẹ, boyá o wà nibi isẹ tàbi o kò si nibi isẹ, só o yé ọ?

    Bẹẹni, sà.

    "Ó dáa, ẹyin èèyàn, fún iyoku akoko isẹ yi, a ó sisẹ lori èrò wipé èniyàn funfun ara Yúrópù tabi Amẹrikà ni bọmbà náà.  Màá kọ iyẹn sinu iwe ipin isẹ wa, sugbọn fun igbà diẹ ná, o sí jẹ́ ìdábàá ni, s’ódáa?  Iyẹn kò di lọwọ, mo tún sọ lẹẹkan si lemọlemọ, ìyẹn kò di lọwọ láti lérò wípé ó se é se kí bọmba náà jẹ́ asẹrùbani Lárúbáwá ló se isẹ búburú yi nitori ọrọ òsèlú tabi ẹsìn.

    Taa lo mọ ohun ti ó wà lọkan ẹniti ó ti setán lati bá Allah padé, ti ó  si nmú awọn aláisẹ pẹlu rẹ? Bóyá ó kàn gbàgbé lati ké Allahu Akbar. Bóyá kò ri idi lati wẹ ojú rẹ laarọ ọjọ yẹn, ti isẹlẹ naa waye.� Máse mu ọkàn kúrò ni ohunkohun to le sẹlẹ. Nkan ti mo nsọ ni wipe fún akoko ipin isẹ yi, a ó lo àbá Suzette to sọ wipe ó se é se ki ó jẹ ara Yúrópù tabi Amẹrika, jẹka sọ pé Òyinbò, ka wò ibiti èyi maa gbé wa dé. Kò si ẹri ìtan kankan ti ó jẹ mọ awọn Oyinbò bọmbà tó npara wọn.

    Awọn èniyàn funfun máa nbọmbù nkan, bẹẹni, ti wọn si nfi ẹtù pàniyàn, bẹẹni, sugbọn wọn ki i sábà pa ara wọn ni sise bẹẹ, ki i se wipe ki wọn pilẹ se ipaniyan náà.

    Arakunrin wa nibiyi wa lẹnu isẹ kan, ó si fẹẹ kú.  Ti ó bá jẹ Òyinbó, a jẹ wipe orisi bọmbà tuntun ti wọn nparawọn ti njade, irú eyi ti kò sẹlẹ ri.

    Ibèèrè. Awọn Oyinbo mélò ni wọn wà nibi isẹlẹ naa nigbati iró naa sẹlẹ? K’ẹnikan s’àwári iyẹn.

    Jẹk’a wòó, awọn eyín-ẹnu mélo ti kò ni oluwa ni a le rí, ati awọn àfọnká eegun? Kó gbogbo wọn papọ lọ fún ayẹwò DNA. Jẹk’á wo boyá a le ri awọn ẹyà ara tí wọn jẹ ti Oyinbó.

    Inu awọn fọrẹnsiki kò ni i dùn si iyẹn, sà.  Yio gbà wọn tó ọsẹ, ti kò bá tó osù.

    Taa ló bikità ohunkohun ti wọn le rò.  Kò sohun ta a le se si; ó se é se ká súnmọ tosi ohun tuntun nibiyi. Ẹgbẹ sẹrùbàwọn tuntun tabi ẹgbẹ tuntun tó yapa kan, botilẹjẹpé mo gbọdọ sọ wipé tó bá jẹ òtitọ, kini’di ti Oyinbo kan fi gbọdọ pa ara rẹ ninu ile itaja Iraki kan?

    Kò fa ọgbọn yọ! Awọn Òyinbò kì í kan se iru nkan bayẹn lati safihan nkankan.

    Njẹ ẹgbẹ kankan ti kede wipe awọn ló s’okunfà isẹlẹ naa bi?

    Rara, sà, kò si nkankan lati orisun wa.

    Se o ti tẹ awọn orisun wa láago, lati bèèrè lọwọ wọn?

    A nse iyẹn lọwọlọwọ bi a ti nsọrọ yi, sà, ati pé ẹnikọọkan  awọn ọga nbèèrè lọwọ awọn tó nta wọn lólobó, sugbọn kò tii si nkankan, kò tii sí.

    Àwọn okunrin to wọ asọ dudu wá awọn kabinẹti ti wọn fi s’àfihàn awọn àlumọni, pupọ ti wọn ti bàjẹ, awọn miran ni wọn bi wó lulẹ.  Awọn okunrin mẹjẹẹjọ náà kó gbogbo ohun ti wọn ri laarin iṣẹjú mẹjọ ti wọn wọlé.

    Olusọ kan tó wà lẹnu àtẹgùn ju mọnamọna àdó olóró silẹ lori àtẹgùn lóórèkóórè ki ó le le àwọn èniyàn sá, kíwọn má ba wá sí òkè tàbí wá si ìsàlẹ, bẹẹ si ni wọn ti jẹki ẹrọ ìgbélọsókè-àti-sisàlẹ duró iṣẹ.

    Wọn kò nilati se ipalára mọ fún ẹnikankan, sùgbọn wọn setán lati se bẹẹ, ti ó bá yẹ.  Niwọnigbati ó jẹ wipé ipele ile keji ni wọn wà, kò sòro fún wọn lati yinbọn si ọkan lára àwọn ferese nla náà, ki wọn si sọkalẹ fúnra wọn sinu mọtò ẹlẹrù tó ndúró si afonifoji nisàlẹ.

    Awọn ọkọ ẹlẹru náà gba ọna miran lọ, kí wọn má ba ri wọn mú. Sibẹsibẹ, wọn di ihámọra, wọn si ni àdó olóró ninu ọkọ kọọkan.  Wọn sálọ láìléwu, wọn si wọ àwọn ọkọ okowò miran ti wọn ni ẹnjini tó ni ilọpo meji agbára, lẹhin ti wọn kúrò ni Scheherazade.

    Gbogbo awọn oludojukọ náà, àyààfi Tony, ni wọn ti wà ni ibi ìpamọ wọn – ilé ọgá wọn – láàárin wákàti kan ti iṣẹlẹ náà ti wáyé.

    Nitorina, Mustapha, sé gbogbo nkan lọ gẹgẹbi a ti sètò rẹ?

    "Bẹẹni, saà. A ti ni awọn ọjà náà láisí jàgidijàgan tabi ki ẹnikẹni kú láarin wa.

    Ètò yin sisẹ dáadáa, saà.

    Bẹẹni, atamátàsé ni nitoripe ó rọrùn. Mo wo ohun gbogbo titi de ibi ti ìbújáde ti sẹlẹ lati ibi kámẹrà ẹni náà lori akìlọ, mo si tún wo bi ẹ ṣe ṣe latibi aworán kámẹrà ìbòrí rẹ bákanna. Aworan lati ibi kámẹrà rẹ kò hàn dáadáa, bóyá nítori eré ti o nsá.

    Mustafa kò fẹ tako ọgá rẹ alágbára, nitori naa, kò sọrọ.

    Bóyá, sà. Ó dáhùn, pẹlú ìrònú wípé ohun tó kéré jù ti òun le se nìyẹn, laimọ̀daju ohun ti ìbá ti jási, àfi ti ó bá dínkù awọn kámẹ́rà asọ́na lókè, gẹgẹbi ó ti sàkiyesi.

    Iwọ ati ẹgbẹ́ rẹ ti se dáadáa, Mustafa ati Èmi kò ní gbàgbé rẹ.̀  Jọwọ ba mi ki ẹgbẹ́ rẹ, kí ó sì dá ọ lójú wípé mo ti pàsẹ fún àwọn ayẹyẹ tí a máa nṣe lẹhin àseyọrí kan. Gbogbo yín ló tọ́ sí.

    Ẹ ṣeun, sà, Màá sọ fún àwọn èèyàn mi.

    Iyẹn tó fún àkókò yìi, Mustafa, simi fún ìgbà díẹ kí o jayé ori rẹ.

    Bẹẹni, sà, Mustafa bẹ́ri fún ọgá rẹ ó sì fi yàrá náà sílẹ.

    Nigbati o ti lọ, Ọ̀gá ki ẹrọ ibanisọrọ rẹ mọlẹ, ó sì tẹ àwọn nọmba kan.

    Ẹgbẹ́ wa borí!  Jẹ́ k’á n’ireti wípé wọn yóò bóri nibi liigi bakanna.

    Ó dáa, ifẹ́ temi náà nìyẹn. Ìgbà wo ni eré tó kàn máa wáyé?

    Nkò ni idaniloju eto yẹn bayi, ṣugbọn mo lero pe ọsẹ díẹ ló kù, ṣugbọn ìta ni a ó ti gba a�bóyá nítòsí rẹ. Ṣe wà á le sètọju wa ti a bá lọ?

    Bẹẹni, Mo lérò wípé mà á le sètò ìyẹn. Sá à ti firanṣẹ simi

    ìwífúnni lẹkunrẹrẹ ìgbà ati iye àwọn tí wọn nbọ̀, mà á si sètò fún itọju wọn.

    Ó dáa. Ìyẹn ni pé kí ngbà wípé wà á sọ fún àwọn ọrẹ wa nípa ìhìn rere yìi?

    Oh, dajudajú! Gbogbo ènìyàn ní ó fẹ dí ajíhìnrere. Mo nreti láti ri.

    Ó digbà kan ná.

    9

    Hello, bẹẹni. Ṣe inú yín dùn sí àwọn esi yẹn, sà?

    Bẹẹni, ohun gbogbo ló lọ déédéé, gẹgẹbi a ti ṣètò rẹ̀. Inú mi dùn gidigidi pẹlú iṣẹ rẹ.

    Ó dáa, Inu mi dùn láti gba ìyẹn. Nitorina, ṣe mo le reti ki o se ojúse rẹ laipẹ?

    "Bẹẹni, a ti ṣètò rẹ̀ sílẹ. Ilé-iṣẹ́ rẹ yíò gba ẹrù lati ọdọ temi laarin ọgbọn isẹju. Ti kò ba ri bẹẹ, jọwọọ tètè kàn sí mi láàrin wakati kan, màá sí yanjú rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

    Se iṣẹ náà máa wà larọwọ to lẹẹkansi?

    Bẹẹni, dajudajú.

    Sé ni àkókò àkíyèsí kan naa?

    Emi kò lè f’ọwọ́sọyà ohunkóhun, àfi ti mo bá rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iwifunni àti àsepari àdéhùn yi bi o ti yẹ.

    Bẹẹni, dajudaju, Mo mọ̀. Mọ̀ dájú pé inú mi dùn púpọ̀ pẹlú iṣẹ rẹ. A ti sètò ohun gbogbo, nitorina jọwọ máa retí ìbéèrè fún ọjà miran láipẹ.

    Gẹ́gẹ́bi o ti sọ, bẹẹni ni a ó se. Inú mi dùn wípé ó ni itẹlọrun pẹlú ile-iṣẹ wa.

    Lẹhinna, ẹrọ ibanisọrọ kò dáhùn mọ́, o sì kàn sí akọwe rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lati ri dájú pé wọn nsan owó lati Switzerland.

    Kò fẹ màgòmágó kankan pẹlú oníbárà yi.

    Ile ifowópamọ́ Swiss kan fi owó  Mílíọ̀nù kan ààbọ̀ Dọ́là ($1,500,000) ranṣẹ ni ọnà kan, ati Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Dọ́la ($500,000) ransẹ ni ọnà miran lai pariwo.

    Isẹ́ míràn tó yọrí sí rere nìyẹn, à Bob.

    Beeni, sà, ó dà bẹ́ẹ̀.

    "Kò sí ìdí tí o ti níláti máa pe mi ni ‘sà’, Bob, àwọn ọjọ yẹn ti kọja tipẹ́tipẹ́, mo sí ti sọ fún ọ ki o pe mi ni Gareg ni ọpọlọpọ ìgbà.

    Bẹẹni, sà, ẹ ti sọ. Máse bínú, kò tíì mọ’ra. Ẹ mase bínú, sà Gareg.

    Jesu, Bob, Sa Gareg tiẹ̀ burú jù"! 

    Ó sọ pẹlú àwàdà.

    Beeni, er, Gareg,  á á mọ́ mi lara lọ́jọ́ kan. Mo lérò bẹẹ.

    Mo n’ireti bakanna. Gbìyànjú láti túraká díẹ síi, a kò sí nínú ologun mọ, a kò sì wà níbẹ fún ọpọlọpọ ọdun. Marun fún ọ, Mẹwa fún mi, mo rò bẹẹ, Abi bẹ́ẹ́kọ́?

    Bẹ́ẹ́ni, saà, Gareg. Mo kúrò ní ọdún mẹrin sẹhin, inú mi yíò sì máa dùn nigbagbogbo pe o wa mi ri o sì tọjú mi. Mo dààmú to jẹ wípé mo nikan wà lori ààtàn, gẹgẹbi ọpọlọpọ awọn agbalagba jagunjagun.

    Bẹ́ẹ̀ni, ṣugbọn, Emi kò ní jẹki ìyẹn sẹlẹ, lẹhin gbogbo ohun ti awa mejeeji ti làkọjá papọ̀, sé màá se bẹẹ?

    Bẹẹni, sà, mo ni, er, Gareg, o ti tun ayé mi se, kò sí asise nípa ìyẹn. Emi àti missus dààmú nípa ohun tí màá se nígbà tí mo bá fẹyinti nínú isẹ ológun, ṣugbọn nibiyi mo ngbà owó ilọ́po mẹta nigbati mo wà lọdọ yín ju ti tẹ́lẹ̀, bẹẹni mo sì tún ngba owo ifẹhinti mi. O kàn wù mi kí alàgbà Jenny wà níbí ki ó lé ri anfaani naa. Sibẹsibẹ, mo jẹ yín nigbese, màá sí máa dúpẹ titi.

    Iyẹn ti tó bayi, jẹ́ka sí ìgò sikọ́shi kan láti se àjọyọ àseyọrí isẹ míràn tí wọn se dáadáa tàbí wàá lọ si ìgboro lati mu’tí rẹpẹtẹ?

    Ọwọ́ yín ló wà, sà, eyikeyi ti ẹ bá fẹ, ó bá mi lára mu.

    O dáa, jẹ́ka ni iyatọ̀ ki á lọ sí ìgboro. Wò ó nípa tani. A máa padà ti kò bá rí bí a se nfẹ.

    Bi o se wà yẹn, ma á gbé ọkọ ayọkẹlẹ wá.  Merc ni tàbí Bentley?

    Oh, Jẹ́ k’á lo Bentley lálẹ oni. Ti a bá mutí pupo jù, o mọ̀ bi yíò se jẹ ìwúrí fún àwọn ọlọpa tó. Kódà a lè se oríire, a à le sọ.

    Bi wọn se fi oko náà sílẹ pẹlú ìdùnnú, dókítà kan láti Birmingham, Alabama, ti ngbiyanju lati pe wọn sugbọn wọn wà lẹnu isẹ, wọn kò sí bikità.

    Wọn kò se. Ni ibi isẹ wọn, kò sí fifagagbága, awọn oníbárà máa npadà wá sọdọ wọn nígbàgbogbo, nitori erè lori idókówò máa npọ̀  gẹgẹ bí àwọn ènìyàn tí lérò sí.

    Owó látọwọ́dọ́wọ́ ti ṣàn désàlẹ̀ gẹgẹbi gbà-má-binu fún àwọọn tó f’arapa nínú iṣẹlẹ bọ́mbù

    Enjoying the preview?
    Page 1 of 1