You are on page 1of 3

CANTO DE IFÁ PARA ÀSÈ De Òsé Òtúrá

Pánsá ojú iná, a bara dúdú petepete Òbùn ló t‟oko bò ló rí sìàsìà D‟ifá
fún olúsólè Ní‟jó ti ó nmú omi ojú sùnráhùn omo Ìgbàtí yó ò bí, ó bí oká
Ó bí eré Ó bí Òpòló Ó bí Òjòlá Ó bí Gùntéré Ekó ni nse omo íkéhin
won lénje-lénje Ekó wá s‟awo re àpá òkun, ìlàmejì Òsà Ìgbàtí yó ò dé,
kò bá Baba mó Ó ní, “níbo ni Baba lo?” Wón ní Baba ti sósún Ó wá to
àwon Babaláwo lo Wón ní ebo ni ko se, pé yó ò rí Babá a rè Ekò rú‟bo
Àwon Babaláwo ré fun ní eyo kòòkan nínú ohon ebo kí ó lo fi bo bàbá
ré Wón ní ti ó bá ti bo Bàbá rè tán, kí ó ma wá baba lo Ekò búrín gàdà,
ó pádé ilá pékí l‟ónà Ilá ní omo olóore òun, “níbo ni ò nlo?” Ekó ní òun
nwá baba lo Ilá fun ni ogún òké owó Ekó búrín gàdà, ó pàdé Ikàn l‟ónà
Ikán ni omo olóore òun, “níbo ni ò nlo?” Ekó ní òun nwá baba lo Ikán
fun ni ogbón òké owó Ekó búrín gàdà, ó pàdé Olóbengán l‟ónà
Olóbengán ni omo olóore òun, “níbo ni ò nlo?” Ekó ní òun nwá baba lo
Olóbengán fun ni ogbón òké owó Ekó tún bùrín gàdà, ilé pin níwájú, ó
pin l‟éhìn Ìgbàtí yó ò gbé esé „kíní, gbé esé ìkejì, ti yó ò gbé ìkéta, ó jín
sí agbede òrun Wón ní, “ògbò nrún” Bàbá a ré ní, “ògbò kò rún” ó ní,
omo òun ni Ó ní, “kíló dé ti ó fi nwá òun bòwá?” Ekó ní nígbàtí óun
dé‟lé, ni wón ní ó ti wá síhìín Ò ní, “Oká ti j‟ogún oró” Ó ní, “Ojòlá ti
j‟ogún òhun” Ó ní, “Opòló j‟ogún éwú ifán” Ó ní, Agùnsóóró j‟ogún
sísán” Ó ní, wón ní ti òun bá súnmo won, àwon yó gbé òun mì Bàbá a
rè bá so àse kansoso tí ó ní kù, sí Ekó ní enu Ó ní kó kálo Ó bá bèrè
sí fi gbogbo áwon nkan ti Ekó fi rú‟bo l‟óde ayé hàa án Ó ní ti Ekó bà
dé‟lé ayé Kí Ekó wí fun won pé Kí wón pa Oká ní àpa dàri Kí wón ma fi
òpá tééré já ìrù Gùntéré Kí wón pa Òpòló, kí wón ma t‟ojú ré bo erè Ó
ní ti ó bá dé‟lé ayé Ti ó bá kan odó nlá ti kò bá lé lo Ó ní ti ó bá ti fi enu
so bèbè ìhín, yó ma bá ara rè ní bàbà òhún Ti ó bá kan igi nlá Ó ní ti ó
bá ti fi enu so bèbè ìhín, yó ma bá ara rè ní bèbè òhún Ó ní ti ó bá kan
òké ti kó le gún-ún Ó ní ti ó bá ti fi enu so bèbè ìhín, yó ma bá ara ré ní
bèbè òhún Ó ní kó di‟jú Ekó di‟jú Baba rè bá gba ní ìdí Ekó bá tún bá
ara rè l‟órí iyorín ní ibi ti ó ti já s‟óde òrun ní àkókó Ìgbàtí yó rín gàdà,
ilá ló túnkó pàdé Ilá ní omo olóore òun niyí láti osù kéta, ó ní, “o rí
baba àbí okò ri?” Ekó ní òun rí baba Ilá ní kínni baba fun Ekó ní ó fun
òun ní àse Ekó ni òun ó tilè dán àse bàbá òun wo Ó ni, “Ilá, èwo ló
ndùn é?” Ilá ni omo ni òun kò rí bí Ekó ní kí ilá ó bí ogún omo Ilá bi
ogún omo Ó ní kí omo „kóókan m aní ogboogbón omo, ogoogún omo
Ó tún pàdé ikán pèkí Ó ní “Ikán, èwo ló ndún é?” Ikán ní omo ni òun kó
rí bíEkò ní kí Ikán ó bí ogboogbòn omo, kí wón m aní àádóta,
ogoogún omo nínù Béèni Ikán se bímo Ó tún pádé olóbengán Ó ní,
“Olóbengán, èwo ló ndìn é?” Olóbengán ní omo ni òun kó rí bí Ekó ní
kí Olóbengán bi ètàlégbéje omo, kí wón m aní ogboogbòn, ogoogóji
omo Béèni dó bengán se bí mo Ekó wá njó, ó nyò, ó nkorin Ó ní: Bí
mo dúró Bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Bí mo bèrè, bí mo wúre Ire è
mi kàsàì gba Baba oká kú, oká jogún oró Bí mo dúró Bí mo wúre Ire è
mi kàsàì gba Bí mo bèrè, bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba… Ohùn: Baba
oká ku, oká jogún oró Ègbè: Bí mo dúró Bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba
Bí mo bèrè, bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Ohún: Baba òjòlá ku, òjòlá
jogún ohùn Ègbè: Bí mo dúró Bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Bí mo
bèrè, bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Ohùn: Baba òpòló ku, òpòló j‟ogún
èwù ifàn
Ègbè: Bí mo dúró
Bí mo wúre
Ire è mi kàsàì gba
Bí mo bèrè, bí mo wúre
Ire è mi kàsàì gba
CANTO DE IFÁ CUANDO SE OFRECE OTÍ (licor) A ÒRÚNMÌLÀ De
Òwónrín Odi (Òwónrín Sìdin)Igún, awo elékòó Akèrègbè mumi f‟òlòlò
s‟éyìn D‟ífá fún won ní wòré wòré ajad Ní ibi ti ikú ti npa wón ní rògbà
rògbà Tó npa wón ní rèwe rèwe Bí eni mú ohun ikú je Njé, gbogbo wa
tó péjú mu‟ti òní Gbogbo w aló ma gbó tìè tìè
CANTO DE IFÁ PARA EL PERDÓN (misericordia) De Ìrosùn Ìwòrì
(Ìrosùn Àwòyè)
Tó bá tó ìje À á se ìje Tó bá tè‟fà À á sè‟fà Tó bá d‟odún
ketàndínlógún Olórò àsài bèrè orò rè D‟ífá fun Òrúnmìlà Ó rán
„Gúnnugún omo rè lo s‟óde Ìwòyè Ìgbà ti è nje igún (buitre) ní ìyà ní
Ìwòyè Èmi ò sí níbè Mbá wà níbè Mbá fi ìróké p‟ogún Mbá wà níbè
Mbá fi ìrùkèrè p‟ogbòn Mbá wa níbè
Mbá fi àdá Òrìsà mi pa àádóta Ìgbà ti è nje igún ní ìyà ní Ìwòyè
Ifá, èmi ò sí níbè.

You might also like