You are on page 1of 9

CHAPTER 4: ÀWỌN ỌNÀ-ÈDÈ TÓ SÚYỌ NÍNÚ ÌPOLONGO ÀRÙN

KÒRÓNÀ
4.1 Oríkì Ọnà-Èdè
Ọnà-èdè tàbí èdè àmúlò ni bátànì ìṣọwọ́lo-èdè tí aṣafọ̀ fi gbé afọ̀ rẹ kalẹ̀. Ohun náà ni a
tún pè ní ìlò-èdè. Ìṣọwọ́lo-èdè tàbí ìlò-èdè ló ń fi bí aṣafọ̀ ṣe dáńgájíá sí nínú afọ̀
gbígbé kalẹ̀ hàn.
Aṣafọ̀ tàbí pèdèpèdè tó bá tó gbangba sùn lọ́yẹ́ nìkan ló ń ṣàmúlò ọnà èdè nínú iṣẹ́ rẹ̀
nítorí wọ́n nílò ojú-inú, àròjinlẹ̀, ẹ̀bùn-ìmọ̀ọ́nṣe, ọgbọ́n-àtinúdá àti ìmèdèélò.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan èròjà tó wà lábẹ́ ọnà-èdè/ìṣọwọ́lo-èdè ló ní àbùdá àdámọ́ tí a fi lè dá a mọ̀ àti
iṣẹ́ tí ó ń ṣe nínú afọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, àbùdá àfiwé tààrà yàtọ̀ sí àwítúnwí, bẹ́ẹ̀ ni àbùdá
àti iṣẹ́ àdàpè yàtọ̀ sí ti àfidípò tàbí mẹ́táfọ̀.
4.2 ÀWỌN ỌNÀ-ÈDÈ TÓ SÚYỌ NÍNÚ ÌPOLONGO ÀRÙN KÒRÓNÀ
Àfiwé
Èyí ni ọ̀nà - èdè tí ó máa ń fi ohun kan méjì wéra lọ́nà tí ọkàn yóò ya àwòrán inú
èkejì síta. Àfiwé ṣe pàtàkì yálà nínú litirésọ̀ àpilẹ̀kọ tàbí alohùn. Akéwì tàbí Aṣafọ̀
fẹ́ràn láti máa fi ohun kan wé òmíràn kí ohun tí ó ń tọ́ka sí bá tètè yé olùgbọ́ tàbí
oǹkàwé náà dáradára, Àfiwé tètè máa ń jẹ́ kí ènìyàn ní òye ohun tí a ń júwe rẹ̀.
Nígbà tí a bá sì jí òye rẹ̀, a ò lè ní inú dídùn sí ohun tí a ń sọ tàbí tí a ń kà.
Oríṣìí Àfiwé méjì ló wà.
(i) Àfiwé tààrà
(ii) Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
Àfiwé tààrà ó ṣòro mọ̀ nínú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ sì ní àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ máa ń farasin nínú
gbólóhùn.

Àfiwé tààrà
Àfiwé tààrà ni kí a fi ohun méji wé ara wọn, kí irú àfiwé bẹ́ẹ̀ sì hàn. Ìjọra tàbí ìyàtọ́
àárín àwọn ohun tí a fi we ara wọn gbọ́ dọ́ hàn ketekete ni. A máa ń lo àwọn atọ́ ka
àfiwe bí, jù àti tó. (------)
Èyí ni kí a fi nǹkan kan wé ohun tí ó jọ́ gan-án láti ya àwòrán wọn sí ọkàn olùgbọ́. Kí
ohun tí a ń sọ yé èniyàn tí a ń júwe rẹ̀ fún dáradára. Aṣafọ̀ kúndùn àti máa lọ àfiwé
tààrà lọ́pọ̀lọpọ̀. Èyí sì hàn nínú ìpolngo dídẹ́kun àrùn covid-19 fún ìlanilọ́yẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ
Bí a bá fi àrùn Kòrónà yìí bí a bá fi ṣe Ògùn àwúre, ó dá mi lójú Olúwa rẹ̀ yóò
lówó ju Dángótè lọ.
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí Aṣafọ̀ fi àrùn Kòrónà yìí wé Ògùn àwúre. Ó ń tọ́ka sì pe, bí Ògùn
àwúre ṣe ń yẹ́ra jẹ́ bí idán bẹ̀ gẹ́lẹ́ ni àrùn Kòrónà yìí ni wọ ni lára kíákíá

Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́
Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ni àfiwé tí a ti ń fi ohun kan wé ohun kan lọ́ nà ẹ̀rọ. Àbùdá tí ohun kín-ín-
ní ní ní a o fi wé àbùdá ti ohun kejì. Halliday (1985:319) fún Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ní oríkì
nígbà tó sọ pé:
“Metaphor is a number of related figures having to do with verbal transference of
various kinds”.
A lè ṣàpèjúwe Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ bí ọ̀nà – èdè Ayàwòrán, èyí ni ọ̀nà tí a fí ń ṣe àfidípò tàbí
ìjọra kan náà. Èyí ni pé ìrísí àti ìṣesí kan pàtàkì máa ń wà láàárín àwọn nǹkan méjì tí
wọn jọ ń ṣe alájọpín àwòmọ́ nǹkan. Ìtumọ̀ àfiwé yìí máa ń yí padà, èyí ní pé ìtumò
wọn máa ń farasin, ó sì máa ń gba àròjìnlẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ :-
Ìgbọràn sàn ju ẹbọ rírú lọ, ká gbọràn sí ìjọba oo
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí Aṣafọ̀ fi Ìgbọràn wé títẹ̀ lé ète àti ìlànà táwọn ìjọba là kalẹ̀, nígbà
tí wọn fi ẹbọ rírú wé wíwá ọ̀nà àbáyọ láti bọ́ lọ́wọ àrùn Kòrónà.
Bí àpẹẹrẹ:-
Ẹní bá rẹ́ yìn ogun ló ń sọ ̀ tàn rẹ̀
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí Aṣafọ̀ rí àrùn Kòrónà gẹ́gẹ́ bí ogun to ń jani. “ló ń sọ ̀ tàn rẹ̀”
fún àwọn tí ó bá sì kogo ja àrùn yìí ní wọn lé e ròyìn rẹ. Èyí ni àwọn tí orí bá kó yọ
lọ́wọ ogun àrùn Kòrónà.
Àwítúnwí
Àwítúnwí ní ọnà èdè tí a fí ń tún fóníìmù, sílébù ọ̀rọ̀, odidi ọ̀rọ̀, akùdé gbólóhùn àtí
odidi gbólóhùn wí nínú ewì Yorùbá. Ìlò àwítúnwí a máa jẹ kí ohun tí akéwì ń wí tàbí
kókó ọ̀rọ̀ tó fẹ́ kó mú àwọn òǹkàwé lọ́ kàn, yóò sì yé wọn yékéyéké nípa ìtẹnúmọ́ .
Oríṣíríṣì ní àwítúnwí tó wà. Àwítúnwí ẹlẹ́yọ-ọ̀rọ̀, Àwítúnwí akùdé gbólóhùn àti
Àwítúnwí odidi gbólóhùn.
Ọ̀nà èdè yìí jẹ ọkan pàtàkì lára ọ̀nà èdè tí ó jẹ mayami fún àwọn Aṣafọ̀, wọn sá bá
máa ń ṣe àmúlò rẹ nínu ẹsẹ-ifá, rárá, ijala, orin àti àwọn mìíràn bẹẹ bẹẹ lọ.
Awitunwi ni kí a má sọ ohun kan ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Àwọn Yoruba bo wọn ní “ìṣù
atẹnumọ̀ràn kí I jóná”wọn a sì tún wí pé “kò kò kò là á rańfá Adití”.
Aṣafọ̀ ṣe àmúlò awitunwi Akude gbólóhùn, èyí ni àwọn awitunwi tí kì rí bákan náà
délẹ̀, ìbéèrè gbólóhùn yóò rí bákan náà ṣùgbọ́n tí ó jé pé ìyàtọ̀ yóò wà kí ó tó dé òpin
gbólóhùn náà. Ìlàjì tàbí díẹ̀ nínú gbólóhùn ni irúfẹ́ awitunwi yìí tí jẹyọ.
Bí àpẹẹrẹ:-
Ẹ fọwọ́ yín pẹ̀lú pẹ̀lú ọsẹ àti omi.
Ẹ lo àwon ohun apakòkòrò bí kò bá sì ọsẹ àti omi.
Ẹ yẹra fún ìbọra ẹni lọ́wọ́ tàbí ìdí mọ́ra ẹni.
E yẹra fún fí fọwọ́ kan ojú, imú, ẹnu pàápàá tí ẹ kò bá fọwọ́ yín.
Ẹ gbìyànjú láti máa fi pépà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bo imú àti ẹnu, bí ẹ kò bá ní pépà, tí ẹ sì fẹ́
sín tàbí húkó, ẹ ṣe sí ìgbọ̀n ọwọ́ yín.
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, a ṣe awitunwi Akude gbólóhùn, èyí sì jẹyọ nínú àwọn gbólóhùn tí
a fàlà sì abẹ́ wọn. Àwọn bí - Ẹ fọwọ́ yín, Ẹ lo, Ẹ yẹra, Ẹ yẹra, Ẹ gbìyànjú. Aṣafọ̀
hún àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pọ̀, bí ó sì ti ń hun ọkàn tán, yóò tún náwó mú òmíràn eléyìí sì
wá jẹ́ kí ẹwà ìpolongo rẹ jáde. Gbogbo ìhun lo ni ise pàtàkì tí wọn ń ṣe, gbogbo afọ̀
gbólóhùn yí dabi Àlùbọ̀sà tí ó ń sì lawelawe, eleyi kò sì ní jẹ́ kí ìpolongo rẹ su
ènìyàn nítorí iparọ ọ̀rọ̀ - ẹnu tí ó lo àti ọ̀nà àrà tí ó gba hún afọ̀ rẹ.
Awitunwi ẹlẹ̀yọ ọ̀rọ̀:
Aṣafọ̀ ṣe àmúlò awitunwi ẹyọ ọ̀rọ̀ ni ìtún jẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo léraléra. Ó jẹ́ àtúnsọ tàbí
ìtẹ́numọ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo. Èyí sì máa ń wáyé leemji tàbí jù bẹẹ lọ nínú ìṣe ọ̀nà Afọ̀
kan, ó si tún lè jẹyọ lórí ìlà kan náà ṣíṣe ìtẹ́numọ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo léraléra wọ́pọ̀
láwùjọ Yorùbá nítorí ọ̀nà láti lè gbà koko oro naa wọlé létí tàbí lọ́kàn ẹni tàbí létí
olùgbọ́ tí á ń fi ìpolongo náà jí’se fún. Ìṣe ìpè akeyesi ènìyàn sì koko kan ni awitunwi
ẹlẹ́yọ ọ̀rọ̀ ń ṣe. Aṣafọ̀ sí ṣe àmúlò irúfẹ́ awitunwi yìí dáradára. Awitunwi ẹlèyọ kìí jẹ́
kí ìtumọ̀ pọn-ọn - na wáyé. Irúfẹ́ awitunwi yìí wọ́pọ̀ nínú òwe Yorùbá.
Bí àpẹẹrẹ :-
Ẹ fọwọ́ yín pẹ̀lú ọsẹ àti omi, Ẹ lo àwon apakòkòrò bí kò bá sì ọsẹ àti omi.
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, a dárúkọ ọsẹ àti omi a sì ṣe awitunwi ọsẹ àti omi Ní emeji nínú
ìpínro kan ṣoṣo, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé iwọnba tí àwa fà jáde ní emeji. Ìdí sì ni láti ṣe àfàyọ
ìṣe pàtàkì ti ọsẹ àti omi Kò nínú ìpolngo tí Aṣafọ̀ ṣe láti fi fọwọ́.
Bí àpẹẹrẹ:-
Ko má yà ni ilé mí, ilé mí, àìsàn búburú, àìsàn
Búburú Kòrónà. Kò má yà ni ilé mí ehen Kòrónà ooooo
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí a ṣe awitunwi àwọn ọ̀rọ̀ tí a fà ìlà sì lábẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí awitunwi tí
Aṣafọ̀ lo láti tẹnu mọ iṣẹ́ afọ̀ ọ̀nà rẹ láti jí isẹ́ fún àwùjọ
Awitunwi ìtumò:-
Èyí ni ṣíṣe awitunwi tàbí ìtẹ́numọ́ ohun kan ní onírúurú ọ̀nà lọ́nà tí irúfẹ́ Afọ̀ tàbí
gbólóhùn náà yóò fún wa ní ìtumọ̀ kan náà. Èyí ni kí iyato díẹ̀ díẹ̀ bá ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin
gbólóhùn, kí ó sì fún wa ní ìtumọ̀ kan náà. Ìṣẹ́ tí irúfẹ́ awitunwi yìí ń ṣe ní pe kii jẹ́ kí
ìṣe ọ̀nà su ènìyàn, ó sì ń mú ẹwà bá irúfẹ́ ìṣe ọ̀nà. Bákan náà, irúfẹ́ awitunwi yìí a
máa fi onísẹ́ ọ̀nà ọlọ́pọlọ̀ pípé hàn yàtọ̀ sí àwọn tí kò dangajia.
Bí àpẹẹrẹ :-
Ẹ fọwọ́ yín pẹ̀lú ọsẹ àti omi,
Ẹ lo àwon apakòkòrò bí kò bá sì ọsẹ àti omi.
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí Aṣafọ̀ sọ ọ̀rọ̀ kan náà ni onírúurú ọ̀nà tí ó fi lé wọ ni létí kí ó sì
dùn mọ ènìyàn, ọ̀rọ̀/ìpolongo ìmọ́tótó ara ẹni tàbí ọwọ́ fífọ́. Àwọn gbólóhùn òkè yìí
túmọ̀ sí ohùn kan náà tí Aṣafọ̀ sọ ní onírúurú ọ̀nà, Ẹ fọwọ́ yín pẹ̀lú ọsẹ àti omi, Ẹ lo
àwon apakòkòrò bí kò bá sì ọsẹ àti omi. Èyí fún wa ní ìtumọ̀ kan náà pé fífọ́ ọwọ́
tàbí ṣíṣe ìmọ́tótó lè dẹkùn àrùn Kòrónà láwùjọ.
Bí àpẹẹrẹ :-
Ẹ yẹra fún fí fọwọ́ kan ojú, imú, ẹnu pàápàá tí ẹ kò bá fọwọ́ yín
Àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí a dá ìlà sì lábẹ́ wonyi fún wa ní ìtumọ̀ kan náà (ìtumọ̀ jìn-jìnnà sí tàbí
yí-yẹra) sì ohun tí ó lè fà àrùn Kòrónà.
Ìbéèrè pèsìjẹ
Ìbéèrè pèsìjẹ ni ìbéèrè ti òǹkọ̀wé bèèrè èyí tí kò réti ìdáhún láti ọ̀dọ̀ ẹnìkankan. Àwọn
akéwì a máa lo ọnà èdè yìí láti fìdí kókó ọ̀rọ̀ múlẹ́ ní. Richard, Platt àti Plait
(1992:136) fún ìbéèrè pèsìjẹ ní oríkì nígbà tí wọ́n sọ pé:
“Rhetorical question is a forceful question which has the form of a question but which
does not expect an answer”.
Èyí ni ìbéèrè tí Aṣafọ̀ béèrè lọ́wọ́ olùgbọ́ tàbí ọnkàwé tàbí akópa mìíràn nínú ìpolngo
náà tí kò sì retí kí ó dáhùn rẹ, bí kò ṣe pé kí ènìyàn ronú lè ìbéèrè náà, lóri ìlànà
ìbéèrè ni ó máa ń gbà wáyé.
Bí àpẹẹrẹ:-
Kí ló dé?
Ó tó bẹ́ẹ̀, ó ju bẹẹ lọ.
A rí pé ìbéèrè yìí jé ìbéèrè pajawiri. Aṣafọ̀ ló ń béèrè ìbéèrè yìí nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn
náà gba a fẹnu sọ,ti o n bá ọmọdé àti àgbàlagbà lẹ́rù.
Bi àpẹẹrẹ:-
Àrùn Kòrónà yìí mo fẹ́ bí yín
Ẹ gbọ́ ẹ́bi ta ni?
COVID-19 yìí, wàhálà ta ni?
Làásìgbò ta ni?
Ẹ jẹ́ a máa bí ara wa lérè
Bi Aṣafọ̀ ṣe hún àgbékalẹ̀ ìbéèrè náà, lọ́nà tí ó jé pé, kò fi àyè sílè fún ìdáhùn bí kò ṣe
láti lè ronú lè ẹ lórí, àti láti sí ọkàn wọn payá lórí ìpolongo àjàkálẹ̀ àrùn aifojuri
Kòrónà
Ìfọ̀rọ̀dárà
Fífi ọ̀rọ̀ dárà ní kí a fi ọ̀rọ̀ tí ẹ̀dà wọn jọra gbe ara wọn ní ọ̀nà àrà. A lè fi sílébù dárà a
sì le fi ọ̀rọ̀-orúkọ tàbí ọ̀rọ̀-ìṣe dárà. Leech (1969) ṣàpèjúwe ìfọ̀rọ̀dárà nígbà tó sọ pé
“Pun is an ambiguity, specifically a foregrounded lexical ambiguity.”
…………….. .
Ìfohunpènìyàn/ Ìfènìyànpohun
Ìfohunpènìyàn máa ń wáyé nígbà tí a bá gbé ìwà, ìṣe tàbí àbùdá ọmọ ènìyàn wọ ohun
tí kì í ṣe ènìyàn bí igi, ẹranko, tàbí ohun àfòyemọ́ , kí ó sì máa hùwà bi ènìyàn.
Bí àpẹẹrẹ:-
Ifohunpeniyan n tí Aṣafọ̀ ṣá mú lò sodo sì ọ̀nà méjì
“ E tẹ etí sí ìkéde pàtàkì yìí kòkòrò korona tí ó ń jà ènìyàn lásìkò yìí”
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí Aṣafọ̀ gbé isesi àti ìrísí ènìyàn wọ “Arùn Kòrónà tí ó ń jà ènìyàn
lásìkò‘’ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó ní bá akegbe rẹ ja. Èyí tún fi hàn bí Aṣafọ̀ ṣe ń lọ àrùn
Kòrónà bí ohun ẹlẹmi. láti mu kí ìṣe ọ̀nà wọn jọjú lójú àwọn olùgbọ́ tàbí àwùjọ.
Bi àpẹẹrẹ:-
Ìfohunpènìyàn ti Aṣafọ̀ tún gbé wọ àrùn kòrónà
“Corona virus àlejò lo jẹ́ ó tí ó pa ènìyàn káàkiri àgbáyé, kò mọ olówó kò ya
táníkà sọ́ tọ,kò mọ àgbàlagbà rárá o”.
Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, Ìfohunpènìyàn ni Aṣafọ̀ gbé wọ “corona virus” isesi àti hùwà sí
ènìyàn ni Aṣafọ̀ gbé wọ “corona virus”. Apànìyàn tàbí aṣọnípa ni ó máa ń pa ènìyàn
káàkiri àgbáyé, corona virus wá ń hùwà bí ènìyàn. Èyí mú kí ìṣe Aṣafọ̀ wuyi púpọ̀.
Ọ̀RỌ̀ ÀYÁLÒ
Ọ̀rọ̀-Àyálò
Ọ̀rọ̀-àyálò ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a yá wọnú èdè Yorùbá láti inú èdè mìíràn. Inú èdè Gẹ̀ẹ́sì ni
èdè Yorùbá ti yá ọ̀rọ̀ jù. Hartmann àti Stork (1972:134) sọ pé:
“Loan words are words introduced into a language directly from a foreign language or
by translation or imitation of a concept taken over from another language.”
Ọ̀rọ̀ ayalo ni yíyá ọ̀rọ̀ kan wọnú èdè kan láti inú èdè mìíràn. Ọ̀rọ̀ yíyá jẹ́ ọ̀nà kan
pàtàkì tí a lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára ọ̀nà tí Yorùbá fi ń dàgbà sókè láti ìgbà- dé-
ìgbà, ohun tí ó jé Aṣafọ̀ lógún ni pé ọ̀rọ̀ tí a bá yá wọnú irúfẹ́ ìṣe ọ̀nà Aṣafọ̀, gbọ́dọ̀
tẹ́le ìlànà àgbékalẹ̀ èdè Yorùbá, ó sì gbọ́dọ̀ bá ààyè tí a ti lo o mú. Nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì ni
Aṣafọ̀ tí ṣe àyálò àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lo nínú ìpolongo rẹ :Bí Bí àpẹẹrẹ:-
Àpẹẹrẹ:
i. “Ìgbọ́ràn ju ẹbọ rírú lọ
Ká gbọ́ràn sí ìjọba o
Make we na obey o”.
…………….
Bí àpẹẹrẹ:-
ii. “Àjàkálẹ̀ Corona Virus
Tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Covid-19
Ogúnlọ́gọ̀ ọmọ ẹ̀dá ènìyàn ló ti rán lọ sọ́rùn àpàpàndodo káàkiri àgbálá ayé”
………….
Bí àpẹẹrẹ :-
iii. “Ẹ má jẹ́ á tàpá sófin o
Kó nílé ó gbélé
Stay at home
Ẹ má jẹ́ á tàpá sófin wọn”
…………
ỌFỌ̀
Ọfọ̀ jẹ́ ẹ̀dọ̀ki agbára ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn Yorùbá láti yí ohun buruku padà sí rere. Ọfọ̀
Yorùbá máa ń ní àpè, gbólóhùn máyẹ̀ àti iṣẹ́ tí ọfọ̀ fẹ́ jẹ́. Olatunji (2005:139) sọ sí èyí
nígbà tó sọ pé:
“Incantation is a restricted poetic form, cultic and mystical in its expectations.”
Ọfọ̀ gẹ́gẹ́ bí èwo àwise Yorùbá jẹ́ ọ̀kan lára afọ̀ alohun tí ó jẹyọ nínú ìpolongo
dídẹ́kun àrùn Kòrónà fún ìlanilọ́yẹ̀ làwùjọ. Aṣafọ̀ ṣe àmúlò ọfọ̀ láti ṣe àfihàn agbára tí
ó wà nínú ọfọ̀.
Bí Àpẹẹrẹ:- ̀
“Ọmọ ọwọ ́ kìí kú lójú ọwọ ́
Ọ mọ ẹsẹ ̀ kìí kú lójú ẹsẹ ̀
Ẹnu, ẹnu báyìí lẹsẹ ̀ fi ń pa èkùrọ ̀ ojú ọ̀nà
Ta ba ni a óò mú òní, ọ ̀ la la óò mú”
Ọfọ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ọfọ̀ àgbélépọ̀tá. Nínú èyí tí à ń pa láti fi sọ ìmọ̀ tàbí èròńgbà ọ̀tá
dasán lórí ayé ẹni.Tí a bá wo ỌFỌ̀ yìí dára-dára a rí i pé ọ̀nà mẹ́ta lọ pín-sín...
Ọmọ ọwọ́ kìí kú lójú ọwọ́
Ọmọ ẹsẹ̀ kìí kú lójú ẹsẹ̀
Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, Oǹpọfọ̀/Aṣafọ̀ ń ṣàfihàn ara rẹ̀ bí ẹni tí ikú ò tọ́ sí. Nítorí gbólóhùn
máyẹ̀ ni ọfọ̀ tó ń pè lenu náà jẹ́. Ẹnu, ẹnu báyìí lẹsẹ ̀ fi ń pa èkùrọ ̀ ojú ọ̀nà.
Ìtumọ̀ èyí ni pé, àrùn náà yóò máa ṣe gbogbo rẹ lórí asán ni lórí ayé òun. Àti pé
gbogbo ìlà kàkà àrùn yìí lórí òun ni yóò máa já sí pàbó. Ó túmọ̀ sí pé, ìgbìyànjú tí kò
le è yọrí sáyọ̀ ni àrùn yìí rawọ́ lé.
Ta ba ni a óò mú òní, ọ̀la la óò mú”
Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, *oǹpọfọ̀/Aṣafọ̀ kò ṣe é mú bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe é pa. Àti pàápàá, bí àrùn yìí bá
tilè tẹ̀síwájú nípa lílé pa òun, ẹni ẹlẹ́ni ni yóò jìyà ibẹ̀.
Gbólóhùn máyẹ̀ ni àwọn ọfọ̀ tí Aṣafọ̀ ṣá mú lò nínú ìpolongo yìí ohun tí a dáyé bá
tàbí gbọ́njú bá tí a gbà pé wọn kò le è yí padà bí ayé bá ń jáyé. Bí ó ti wà ní
àtètèkọ́ṣé, bẹ́ẹ̀ ló wà ní ìsinsìnyí, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì máa rí nígbà gbogbo, ayé àìnípẹ̀kun)
Kò dá, òótọ́ ayérayé ni pẹ̀lú, tí kò sì le è yí padà nígbà kankan
…………….

……………
….
Ìlò òwe
Ìlò òwe a máa kúnnú ewì dẹ́nu. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé ‘òwe lẹṣin ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀
L’ẹṣín òwe, bí ọ̀rọ̀ bá sọnù òwe la ó fi wá a. Norrick (1985) sọ pé:
“A proverbial image is a concrete description of a scene, which can be
generalized to yield an abstract truth.”
Òwe jẹ́ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àwọn Yorùbá tó ń jẹ yọ láti inú ìrírí, òye, ìṣẹ̀lẹ̀ àti
àkíyèsí wọn nípa àwùjọ àti gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá.
Ìbádọ̀gba Gbólóhùn
Is̩ ẹ́ gbólóhún adọ́ gba ni ìte̩numọ́ . Àwọn gbólóhùn adọ́ gba wọ̀nyìí ní ìlò ifọ̀rọ̀-gbé-
ọ̀rọ̀ díẹ́. Bákan náà ni ìhun àwọn gbólóhùn inú ewì náà le dọ́gba ní ìhun òòró àti
ìhun ìbú.
Yankson (1987:14) sọ sí èyí nígbà tó ní:
“Parallelism is meant by the use of pattern repetition in a literary text for a
particular stylistic effect.”
Àkànlò-èdè
Àkànlò-èdè ni ìpèdè tàbí gbólóhùn tí àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àkóónú rẹ̀ kò níí ṣe pẹ̀lú
ìtumọ̀ tí irú ìpèdè bẹ́ẹ̀ ní. Ìyẹn ni pé, a kò lè ti ara àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àkóónú ìpèdè
tàbí gbólóhùn náà mọ ìtumọ̀ rẹ̀.

Ẹ̀ dà-Ọ̀rọ̀
Ẹ̀ dà-ọ̀rọ̀ ni kí a sọ̀rọ̀ kan ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ìdàkajì rẹ̀ ni a ní lọ́kàn.
Ọ̀rọ̀-Àyálò…. Still working ọn the explanation of this.
Ọ̀rọ̀-àyálò ni àwọn ọ̀rọ̀ tí a yá wọnú èdè Yorùbá láti inú èdè mìíràn. Inú èdè Gẹ̀ẹ́sì
ni èdè Yorùbá ti yá ọ̀rọ̀ jù. Hartmann àti Stork (1972:134) sọ pé:
“Loan words are words introduced into a language directly from a foreign
language or by translation or imitation of a concept taken over from another
language.”
Àpẹẹrẹ:
i. “Ìgbọ́ràn ju ẹbọ rírú lọ
Ká gbọ́ràn sí ìjọba o
Make we na obey o”
ii. “Àjàkálẹ̀ Corona Virus
Tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Covid-19
Ogúnlọ́gọ̀ ọmọ ẹ̀dá ènìyàn ló ti rán lọ sọ́rùn àpàpàndodo káàkiri àgbálá ayé”
iii. “Ẹ má jẹ́ á tàpá sófin o
Kó nílé ó gbélé
Stay at home
Ẹ má jẹ́ á tàpá sófin wọn”
These bold example aré not among those listed above examples
Thanks sọ much sir.

You might also like