You are on page 1of 9

Ìbà: Èròjà Kò-ṣeé-mọ́ -nì-ín fún Lítíréṣọ̀ Alohùn Yorùbá

Ọládélé Caleb Orímóògùnjẹ́, Ph.D.

Ìfáàrà
Yorùbá bọ̀ wón ní a kì í ṣòòṣà lódò kí làbẹlàbẹ má mọ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọ̀rọ̀ ìjúbà rí nínú
Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá. Ìdí ni pé kò sí agbátẹrù Lítíréṣọ̀ alohùn tí kò ní fi ti ìbà ṣáájú
ohun gbogbo. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn ni pé, ọ̀bẹ àwọn alayé yóò bá a.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ pé bí lítírésọ̀ àpilẹ̀kọ ṣe wà náà ni Lítíréṣọ̀ alohùn wà, èyí ló sì ti wà
láàrin àwọn Yorùbá kí àwọn Gẹ̀ẹ́sì tóó dé. Bákan náà ni ọ̀bọ àti ìnàkí àwọn mẹ́jéèjì
(Lítíréṣọ̀ alohùn àti àpilẹ̀kọ) ṣe ṣorí. Lítíréṣọ̀ alohùn yìí jẹ́ ọ̀nà kan gbóógí tí àwọn ẹ̀yà
Yorùbá (àti ẹ̀yà mìíràn) ń gbà fi èrò wọn nípa àṣà wọn han àwùjọ àṣùwàdà ènìyàn.
Orísìí ì́sọ̀rí mẹ́ta ni Lítíréṣọ̀ alohùn ní: ewì, Eré-oníṣe àti Ọ̀rọ̀-geere. Àwọn tó jẹ́
agbáterù ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan kì í tẹ́ pẹpẹ eré wọn kalẹ̀ láìfi ti ìbà ṣe. Lọ́rọ̀ kan, tí a bá sọ pé
‘kò sí nílùú, ìlú kò dùn’ ni ìbà jẹ́ lára Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá, kò léèwọ̀.

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kì í perí ajá, kí a má perí ìkòkò tí a fi sè é tí ọ̀rọ̀ ìbà jẹ́ nínú
Lítíréṣọ̀ alohùn, ló jẹ́ kí ó jẹ wá lógún láti wo ìpa tó ń kó nínú Lítíréṣọ̀ alohùn, ìhà tí
Yorùbá kọ sí i àti oríṣirísi ọ̀nà tí wọ́n ń gbà júbà, yálà nínú Lítíréṣọ̀ alohùn tàbí nǹkan
mìíràn ní àwùjọ Yorùbá.

Bí Ìṣọ̀lá (1976) ti ṣiṣẹ́ lórí ìbà gẹ́gẹ́ bó ṣe wáyé nínú ewì alohùn lápapọ̀, náà ni Àlàbá
(1985) ṣiṣẹ́ lórí ipa tí ìbà ń kó nínú orin agbè. Lórí ewì alohùn ni àwọn onímọ Lítíréṣọ̀
méjéèjì wọ̀nyí ti ṣiṣẹ́ lórí ìbà, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yìí wo ipa tí ìbà kó nínú Lítíréṣọ̀ alohùn láti
òkè délẹ̀. Lọ́rọ́ kan ṣá, bí ìbà ṣe ń wáyé àti ìlò rẹ̀ nínú ewì alohùn, ọ̀rọ̀-geere alohùn àti
eré-oníṣe alohùn ni iṣẹ́ yìí gbé yẹ̀wò. Bẹ́ẹ̀ náà la ṣàyẹ̀wò bí wọ́ n ṣe ń ṣàmúlò ìbà nínú
àwọn iṣẹ́ àṣelà láwùjọ Yorùbá.

Kí ni Ìbà?
Ní àwùjọ Yorùbá, ìbà jẹ́ nǹkan tó pọn dandan láti ṣe fún ẹ̀dá tó bá fẹ́ dáwọ́lé nǹkan,
pàápàá nǹkan tí ẹni náà mọ̀ pé àwọn kan ti ṣe irúfẹ́ rẹ̀ rí. ìbà kì í se nǹkan kèrémí ní
ààrin àwọn Yorùbá; ó jẹ wọ́n lógún gan-an, kódà, wọn a máa kan oró ẹni tí kò bá júbà
mọ́nú.

Ìjúbà ni a rí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan pàtàkì lára ìṣe Yorùbá tó máa ń mú ẹ̀ dá mọ ibi tí iṣẹ́, ìṣe,
ìdílé àti ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ti ṣẹ̀ wá. Ó jẹ́ dúkìá kò-ṣe-é-má-nì-ín tó wà fún ìṣọ́rí, tí kì í jẹ́
nǹkan tí ẹ̀dà ń ṣe lọ́wọ́ hun ún. Abájọ tí Yorùbá fi ń sọ pé ‘Àdáṣe níí hunni, ìbà ò
gbọdọ̀ hunmọ ènìyàn.

Àwọn Yorùbá tún ka ìbà sí ọ̀nà tí wọn ń gbà tẹríba tàbí wárí fún Olódùmarè, àwọn
irúnmọlẹ̀, àwọn alayé, àgbà iwájú, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn. Ìdí rèé tí
wọ́n fi ń sọ pé ‘mo júbà ará iwájú káyé ó le yẹ mí, mọ ṣèbà èrò ẹ̀yìn, kẹ́yẹ má baà
yọ̀wú mi jẹ’, Ẹni tó bá ń tẹríba fún ọmọ aráyé, nǹkan yóòwù kí onítọ̀ hún dáwọ́lé, ó di
dandan kí ó kẹ́sẹ járí; tirẹ̀ ni yóó sì máa wu ọmọ adáríhurun.

Bákan náà ní àwọn Yorùbá gbà pé ìbà jẹ́ ọ̀nà ẹ̀rọ tí wọ́n ń lò láti bu ọlá àti ọ̀wọ̀ fún ẹni
tó jẹ́ aṣáájú nǹkan tí wọn ń ṣe. ọ̀rọ̀ àánú, ire àti ìre yóó sì máa jáde lẹ́nu ẹni tí wọ́n ń
fìbà fún. Ìdí sì rèé tí wọ́n fi mú ìbà ní ọ̀kúnkúndùn kí àṣeyọrí àti ìdágìlọ ire baà lè jẹ́
tẹni. Lọ́rọ̀ kan ṣá, a lè sọ pé ìba-jíjú jẹ́ okùn orí-ire àti ìdùnnú fún ọmodé, àgbà, àwọn
òòṣà àti nǹkán ẹlẹ́mìí mìíràn ní àwùjọ Yorùbá. èyí ló jẹ́ kí a pe ìba ní kẹ̀kẹ́ ìhìn-rere
fún Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá.

Ìhà tí Yorùbá Kọ sí Ìbà


Oríṣiríṣi èrò ni àwọn Yorùbá ní lórí ìbà: èrò wọ̀ nyí sì dúró lórí ìhà tí wọ́n kọ sí i àti
ìgbàgbọ́ wọn lórí rẹ̀. Lọ́nà kínní, Yorùbá gbàgbọ́ pé tí ẹ̀dá kan bá ń pète láìjúbá, bí
ìgbà tí onítọ̀hún ń ṣe ìgbéraga àti àfojúdi ni; wọ́n sì lè ka irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sí aláìmoore àti
a-kú-má-mojúú-dì ènìyàn, tí kò mọ rírì àwọn tí wọ́n ti ṣe irúfẹ́ nǹkan náà ṣaájú rẹ̀.
Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá jinlẹ̀ lórí Lítíréṣọ̀ alohùn àti pé kò sí ohun tuntun lókè èèpẹ̀ tí
ẹnìkan kò tíì ṣe ṣáájú rí. Ìdí rèé tí wọ́n fi ka ẹni tí kò bá júbà sí afibisólóore, olè àti
ajẹnisẹ́ ẹ̀dá. Roger (1980: 47 – 49) náà jẹ́rìí sí i pé olè ni ẹni tó da ìwé oníwèé kọ
láìfìbà jẹ́wọ́ ìmúlò fún onínǹkan. Nicholson (1970: 97 – 100) náà kò ṣaláìrí sọ sí èyí.
Fún ìdí èyí, tí agbátẹrù èyíkéyìí nínú ẹ̀yà Lítíréṣọ̀ alohùn mẹ́tẹ́ẹ̀tà bá tẹ́ fádà eré rẹ̀, bí
kò tilẹ̀ mọ ẹni tó kọ́kọ́ dáwọ́lé e ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ó ye kí ó lè júbà pé:

Àtẹ́lẹwọ́ ni mo bálà
N kò mẹni tó kọ ọ́
Bíbá ni mo bórò nílé
Ilé ọkọ ni mo bá ìyá mi
N ò mẹni ó déyìí sílẹ̀
Ìbà lọ́wọ́ ẹni ó kọ́kọ́ dá kí n tó dá

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ẹyẹ tó ṣu nǹkan tó dáwọ́lé ṣùgbọ́ n tó ti júbà olùdásílẹ̀, tí àwọn
ènìyàn ẹni tó kọ́kọ ṣe irúfẹ́ rẹ̀ bá wà ní ìkàlẹ̀, inú wọn yóò dùn pé ó rántí aṣáájú àwọn,
wọn kò sì ní jẹ́ kí ewu wà lọ́nà ẹnu ìlo fún apohùn bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ náà.

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé àṣà Yorùbá ni láti àárọ̀ ọjọ́ wá pé kí wọ́n máa wárí fún aṣáájú ẹni,
èyí sì ti jẹ́ kó wà nínú ẹ̀jẹ̀ wọn tó fi wá di bárakú fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló sì wà nínú ìṣesí
wọn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ọkàn wọn pé tí ẹ̀dá adáríhurun bá kọtí ọ̀gbọn-in sẹ́bọ ìbà, ọkàn
olúwa rẹ̀ kò ní balẹ̀ mọ́; inú-fuu,ẹ̀dọ̀-fuu ni yóò máa fi ṣe nǹkan tó ń ṣe náà. Lọ́kàn
onítọ̀hún, nǹkan tẹ́nìkan ò ṣe rí tóun ṣe yìí yóò jẹ́ kí òun gba èrè ìtìjú. Bó sì ti lè wù kí
ẹni náà mọ̀ ọ́n ṣe tó, àwọn ọmọ Yorùbá yóò dá ‘hẹ̀ẹ̀’ rẹ̀ nítorí pé kò fi tará iwájú àti èrò
ẹ̀yìn se. tó bá jẹ́ pé ó júbà, bí ó tilẹ̀ kù díẹ̀ káà tó, tàbí tí nǹkan náà bá fẹ́ yíi lọ́wọ́,
àwọn aláṣekù yóò tọ́ ọ sọ́nà, kí ó baà lè júṣe fún un.

Lójú àwọn Yorùbá, ìbà ni ó borí ohun gbogbo ní àwùjọ àṣùwàdà ènìyàn. Bó ti wù kí
ènìyàn ó gbọ́n nínú, gbọ́n lẹ́yìn tó, kódà bó gbọ́n ju aṣarun lọ, kó sì tún lóògùn bí
àrọ̀nì, bí ó tilẹ̀ lówó àti ipò ju Eléwì Odò lọ, tó bá fojú kéré ìbà, ayé ìdààmú ní irúfẹ́
ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ wá, nítorí pé bí àwọn Ọ̀-ǹ-nilẹ̀ kò bá gba ẹ̀mí rẹ̀ ní rèwerèwe, eṣinṣin níí yọwó
imí ni gbogbo ìgbèsẹ̀ rẹ̀ yóò máa jẹ́.

Yorùbá ka ìjúbà sí gbèsè tí àwọn ẹ̀dá alààyè jẹ ará ọjọ́un, tó ti fojú winá nǹkan tí wọ́n
ń ̣se. Wọ́n ní eyín kan ni gbèsè ní, tó bá ti kán, ó parí, kí onígbèsè máa lọ ní àlàáfíà ni.
Ẹni tó bá júbà ti kán eyín gbèsè tó jẹ nù un, ṣùgbón ẹni tó bá gbọ́n tán lójú ara rẹ̀, tí kò
fìbà fún àwọn onínǹkan, dandan ni kí nǹkan tó se hun ún, kí ó sì rí ìdààmú tí Ológò ń
fi ojú onígbèsè rí gẹ́gẹ́ bí ojú Ọ̀jẹ́làdé tó kọ̀ tí kò bodè fún àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ ṣe rí àtàlátà
baba àlárúbá nìnú Ògúnníran (1972: 27 – 33). Àìjúbà ni wọ́ n fi dan án nígbà tó di
ọ̀nì, ọpẹ́lọpẹ́ orí inú rẹ̀, ì bá dán an tán.

Ọpẹ́ ni àwọn Yorùbá tún ka ìbà sí. Ìdí sì rèé tó fi jẹ́ pé ẹni tó bá jẹ́ agbátẹrù ẹ̀yà
Lítíréṣọ̀ alohùn kan máa ń lo ìbà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣáájú rẹ̀ tó kọ́ ọ ní dídá-ọwọ́ àti
òtìtẹ̀ alẹ̀, ṣe bọ́mọdé bá dúpẹ́ oore àná, á rí òmíràn gbà. Èyí ni oníjàálá kan òkè ọ̀hún fi
máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó kọ́ ọ lórin ọdẹ pé:

Ìbà lọ́wọ́ Ìṣọ̀lá arígbẹ̀ẹ́yọ̀


Akin nínú ọdẹ
A-májá-lóko-má-mú-un-wálé,
Baba Ògúndípẹ̀
Ìbà lọ́wọ́ baba Ògúnjọkẹ́ ajá-gudugbẹ̀ lẹ́sẹ̀ òkè
Ìbà lọ́wọ́ gbogbo àgbààgbà tá à ń fọlá wọn ọ́n rìn tíkú pa ...

Yorùbá gbàgbọ́ pé tí ènìyàn bá ti ríbà nílé kó tó máa báṣẹ bọ̀, kò ní sí ìṣòro fún un nínú
ìdáwọ́lé rẹ̀, ìbáà se oníjàálá, asùnyẹ̀rẹ̀, apeṣàngó tàbí apohùn mìíràn. Àwọn aṣáájú rẹ̀
yóò máa kọ́ ọ ní nǹkan tí yóò wí láìsí wàhálà, nítorí ọpẹ́ yìí fi hàn pé ó mọ rírì àwọn
aláṣekù.

Láìfepo-bọyọ̀, láìfigbá-ọ̀bọ̀rọ́-bẹ̀ha, kedere ni a rí i báyìí pé ìbà jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìkíni àti
ìmúwásíràn-án-tí àwọn ará ọjọ́un tàbí aṣáájú ẹni tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nǹkan tí ẹni tó júbà
ń ṣe. Bó ṣe ń kí wọn pẹ̀lú ìbà ló ń jẹ́ kí àwọn èrò ìwòran mọ̀ nípa àwọn tó mọ àtiwáyé
ẹ̀yà Lítíréṣọ̀ alohùn tí apohùn ń mú wá sí etígbọ̀ọ́ wọn.

Oríṣìí Ọ̀nà Ìjúbà


Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a ti mọ nǹkan tí à ń pè ní ìbà àti ìhà tí Yorùbá kọ sí i, kò yẹ kí a
má tú u yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ nípa ọ̀nà tí ó lè gbà wáyé láàrin àwọn Yorùbá, yálà nínú Lítíréṣọ̀
alohùn ni tàbí nínú ìṣẹ̀ṣe Yorùba mìíràn.
Ọ̀nà àkọ́kọ́ tí a ó mẹ́nu bà nípa bí wọ́n ṣe ń júbà ni èyí tí a mọ̀ mọ́ Lítíréṣọ̀ alohùn, tí
gbogbo mùtúmùwà máa ń fetí gbọ́; èyí ni fífi ẹnu júbà. Akéwì agbátẹrù eré-oníse tàbí
aṣọ̀ tàn ọ̀rọ̀-geere yóò júbà kó tó bẹ̀rẹ̀ òwò ètè rẹ̀ ní pẹrẹwu. Àpẹẹrẹ asọ̀tàn-ọ̀rọ̀-geere
kan ni Olóyè Odùúṣẹ̀yìndé nínú Ògúnpòlù (1986: 31) tó júbà àwọn abulẹ̀dó tó ṣáájú rẹ̀
pé:

Mo júbà Oṣọ́bíyà
Ìbà á sẹ
Mo júbà Ògìdán
Ìbà á sẹ
Mo júbà Àso
Ìbà á sẹ
Mo júbà agbọ̀nà
Ìbà á sẹ ...

Bí wọ́n ṣe ń júbà ẹni-rírí, ni wọ́n ń júbà ẹni-àìrí àwọn Olóòfiri-ará-odò-alẹ̀. bí àpẹ́ẹrẹ,
asùnjálá kan ló máa ń ríbà lójú agbo báyìí:

Ìbà lónìí
Mo ríbà kí n tó máa lọ
Ìbà lọ́wọ́ọ kékeré ọdẹ
Ìbà lọ́wọ́ àgbààgbà ọdẹ
Ìbà lọ́wọ́ Àwòrò-Ògún tó ń bẹ nílẹ̀ láìkọrin ọdẹ
Ṣé ò ní séwu lọ́nà ẹnuù’lọ?
Kí n máa bórin ọdẹ lọ
Mo júbà lọ́wọ̀ rírí
Ìbà lọ́wọ́ àìrí
Ìbà Ògún onírè ẹdan ajólúwọnran
Koríko odò tíí rú mìnìmìnì ...

Adáhunṣe náà sì lè júbà àwọn aláṣekù gẹ́gẹ́ bó ṣe hànde nínú Orímóògùnjẹ́ (1986: 7)
pé:
Ọ̀sanyìn ‘mọlẹ̀, ó dọwọ́ rẹ
K’ó o jóògùn yìí jẹ́ bí iná
K’ó gbà bí oòrùn
Ijẹ́ iná ni kó jẹ́
Kó má jẹ́ ìjẹ́ oòrùn ...

Yàtò sí ìbà tí wọ́n fẹnu jú, Yorùbá tún máa ń júbà nípa ètùtù ṣíṣe. Tí nǹkan kò bá
rọgbọ fún ẹ̀dá kan, Àwọn akọ́nilọ́gbọ́n-àgbẹ̀dẹ-ọ̀run-í-rọ yóò gbà á ní ìmọ̀ràn pé kó lọ
fi ètùtù ṣèbà, yálà lójúbọ òòṣà ni tàbí lójú oórì àwọn ọ̀ run rẹ̀. Àpẹẹrẹ irúfẹ́ èyí la rí
nínú Abímbọ́lá (1976: 157 – 160) níbi tí àwọn awo ti gba Oyèépolú ní ìmọ̀ ràn pé kí ó
lọ ṣètùtù ní ojú-oórì àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ayé rẹ̀ kò rójú. Nígbà tí wọ́n kó nǹkan orò
sílẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí júbà pé:

B’épo lẹ kọ́ọ́ ta á ‘lẹ̀ ni


Èmi ò mọ̀
Oyèépolú ò mọ̀kan
B’ọ́tí lẹ kọ́ọ́ ta á ‘lẹ̀ ni
Èmi ò mọ̀.
Oyèépolú ò mọ̀kan
Gbogbo ìṣorò ọ̀run
Ẹ súré wá
Ẹ wáá gb’orò yìí se.

Lẹ́yìn ètùtù yìí, a rí i pé ayé Oyèépolú tùbà tùṣẹ, ó sì tòrò bí omi à-fòórọ̀-pọn.

Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ìbà máa ń wáyé gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ aṣáájú ẹni. Ẹni tó fẹ́ láti ṣe
nǹkan yóò lọ gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn tó ti kọ́kọ́ ṣáájú rẹ̀ já ewé nǹkan tó dáwọ́ lé. Èyí
dúró fún pé, ó kágò kó tó wọlé. Inú aṣáájú bẹ́ẹ̀ yóó dùn nítorí pé yóó gbà pé ẹ̀dá bẹ́ẹ̀
mọ̀ pè òun gẹ́gẹ́ bí àgbà ní ìrírí jù ú lọ, àti pé ó kágò kí ó tó dáwọ́ lé nǹkan náà nípa
gbígba ìmọ̀ràn. Èyí kò ní jẹ́ kí ewúrẹ́ oníbèérè bẹ́ẹ̀ dẹran àmúso níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ó
júbà lọ́nà ẹ̀rọ kí nǹkan tó ń ṣe má baà hun ún. Kí Yorùbá tóó bẹ̀rẹ̀ nǹkankínǹkan tó jẹ
mọ́ Lítíréṣọ̀ alohùn, wọ́n máa ń gba ìmọ̀ràn àwọn ògúnná-gb̀ òǹgbò tíí dátọ́ lẹ́nu
ìgbín àti lọ́wọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn tíí moyún ìgbín nínú ìkarahun. Èyí ló sẹlẹ̀ nínú
Ògúnníran (1972: 11) nígbà tí Ọ̀jẹ́làdé lọ gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ Dáṣọfúnjó ọ̀rẹ́ bàbá rẹ̀
Ọ̀jẹ́lárìnnàká pé òun fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àrìnjó tóun.

Àgbálọgbábọ̀
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a rí pé ipa pàtàkì ni ìbà kó nínú Lítíréṣọ̀ alohùn àti àwọn ìṣẹ̀ṣe
Yorùbá mìíràn. Ìdí ni pé wọn kà á sí ọ̀ran-an-yàn láti júbà nítorí pé gbogbo nǹkan tí
ẹ̀dá ń ṣe ni ọ́ jẹ́ pé àwọn kan ló bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ wá, ìbà àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ẹ̀dá
alààyè ń jú. A tún rí ìbà gẹ́gẹ́ bí nǹkan tó fara jọ ọ̀nà tí à ń gbà wárí fún àwọn tó ti ní
ìmọ̀ ṣáájú ẹni nínú ètò mọ̀-ọ́n-kọ-mọ̀-ọ́n-kà tí àwọn òǹkọ̀wé ń se. Bí ìyà ṣe wà fún ẹni
tó bá rú òfin ìjẹ́wọ́-ìmúlò ti ìgbàlódé yìí náà ni ìyà ń bẹ fọ́mọ tó bá ṣe àfojúbi ìbà nínú
Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá.

Nínú ìgbàgbọ́ Yorùbá, ó hàn gbangba pé ìbà ń fi àṣà wọn hàn nípa fífi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
ìmoore àti ìmọrírì aṣáájú ẹni hàn. nínú iṣẹ́ yìí la ti ṣe àkíyèsí pé, kò sí ẹni tó lè fọwọ́
sọ̀yà pé òun ló kókọ́ dáwọ́ lé nǹkan kan nílẹ̀ Yorùbá. Gbogbo ẹ̀yà Lítíréṣọ̀ alohùn
Yorùbá ni àwọn ará ọjọ́un ti ṣe rí. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn agbátẹrù Lítíréṣọ̀ alohùn ló sì
gbọdọ̀ jẹ́ káráyé mọ̀ pé bíbá ni òun bá orò nílé àti pé ilé ọkọ ni kóówá bá ìyá rẹ̀.

Ó hàn kedere pé láàrin àwọn Yorùbá, ojú olè, onígbèéraga, aláfojúdi àti aláìmoore ni
wọ́ n máa ń fi wo ẹni tí kò bá fi ìbà fún àwọn ará iwájú tó mọ ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nǹkan tó ń ṣe.
Ìyà mánigbàgbé sì ni irúfẹ́ ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ ní àwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé
Yorùbá ní ìgbàgbọ́ pé kíkí ẹ̀dá alàáyè nìkan kọ́ ló wà ní àwùjọ àti pé àwọn ẹ̀mí àìrí náà
ń bẹ tí ẹ̀dá alààyè gbọdọ̀ máa bu ọlá fún.
Àkójọ Orúkọ Ìwé
Abimbola, W. (1976). Ifá: The Exposition of Ifa Literary Corpus. Ibadan: Oxford
University Press. Alaba (1985)
Idowu, E. (1962). Olódùmarè: God In Yorùbá Belief. Ikeja: Longman Nigeria
Limited.
Isola, (1976). “The Place of Ìbà in Yoruba Oral Poetry” Proceedings 12th West
African Linguistics Congress, University of Ife April 16th, 1976.
Nicholson, M. (1970). A Manual of Copyright Practice. New York: Oxford University
Press.
Oduyoye, N. (1971). The Vocabulary of Yorùbá Religion Discourse. Ibadan: Daystar
Press.
Ogunniran, (1972). Eégún Aláré. Lagos: Macmillan Nigeria Publishers Ltd.
Ogunpolu, I. 91985). “Classification of Yorùbá Prose Narratives: A New Perspective”
Seminar on Yorùbá Folklore. Ogun State University.
Olumide, L. (1948). The Religion of the Yorùbá. Lagos: CMS Bookshop.
Orímóògùnjẹ́, O. (1980). Ọdún Ọ̀ sanyìn Ní Ìlú Osùn-ún Èkìtì. B.A. Thesis Ọbáfẹ́mi
Awólọ́ wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.
Olajubu, O. (1985). “Oríkì” Yorùbá Gbòde cl. 2, No. 3: 15 – 27.
Roger, L. (1980). Research Method. Prentice Hall: Eaglewood Cliffs.
Ìbà àti Litt. Alohùn

You might also like