You are on page 1of 1067

1

C.M.
Ago Re wonni ti li ewa to, Oluwa awon omo ogun. OD. 84 : 1.

1. f Olus’aguntan eni Re
Fi are Re han wa,
‘Wo fun wa n’ile adura
M’okan wa gbadura.

2. mf Fi ami ife Re han wa


So ireti wa ji
Se ‘ri’bukun Re s’ori wa
‘awa le ma yin O.

3 mf K’ife ati alafia


K’o ma gbe ile yii
F’irora f’okan iponju
M’okan ailera le.

4 mf F’eti igbo, aya ‘gbase


Oju ‘riran fun wa;
Tan imole Re lat’oke
K’a dagba l’or’ofe.

5 mf K’a fi ‘gbagbo gbo oro re


K’a f’igbagbo bebe
Ati niwaju Oluwa
K’a se aroye wa.
Amin
2
8.7.8.7
Oluwa fi igbala re be mi wo OD. 106:4 .

1 f Ife orun, alail’egbe,


Ayo orun sokale,
Fi okan wa se’bugbe Re,
Se asetan anu Re.

2 Jesu Iwo ni alanu


Iwo l’onibu ife
cr Fi igbala Re be w a wo
M’okan eru wa duro.

3. mf Wa, Olodumare, gba wa


Fun wa l’ore-ofe Re
L’ojiji ni k’opada wa,
Ma si fi wa sile mo;.

4 f Iwo l’a o ma yin titi,


Bi won ti nse ni orun
Iyin w ki yoo lopin
A o s’ogo n’nu ’fe Re.

5 cr S’asepe awa eda Re


Je k’a wa lailabawon
K’a ri titobi ‘gbala Re
Li aritan ninu Re.

6 ff Mu wa lat’ogo de ogo,
Titi de ibugbe wa;
T’ao fi ade wa juba Re
N’iyanu, ife, iyin.
Amin.
3
L.M
Emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD 103:2

1 f Ji okan mi, ba orun ji,


Mura si ise ojo Re,
Mase ilora, ji kutu,
K’o san ‘gbese ebo oro.

2 Ro gbogb’ojo t’o fi sofo


Bere si rere ‘se loni
Kiyesi ‘rin re l’aye yi,
Ko si mura d’ojo nla ni.

3 mf K’oro re gbogbo j’otito,


K’okan re mo b’osan gangan
Mo p’Olorun nso ona re
O mo ero ikoko re.

4 f Nipa ‘mole ti nt’orun wa,


Tan ‘mole na f’elomiran;
Jeki ogo Olorun ‘han
Ninu ife at’orin ‘yin.

5 f Ji, gbonranu’wo okan mi,


Yan ipo re l’arin Angeli’,
Awon ti won nkorin iyin
Ni gbogbo igba s’Oba wa.

6 Mo ji, mo ji, ogun orun,


Ki isin yin s’okan mi ji,
Ki nle lo ojo aye mi,
Fun Olorun mi bi ti yin.
Amin.
4
L.M.
Ma rin niwaju mi, ki iwo ki o si pe. Gen. 17 : 1.

1. mf Oluwa mi, mo njade lo


Lati se ise, oojo mi;
Iwo nikan l’emi o mo
Loro, lero, ati n’ise

2. Ise t’o yan mi l’anu Re


Jeki nle se tayotayo
Ki nr’oju Re n’nu ise mi,
K’emi si le fi ‘fe Re han.

3 . Dabobo mi lowo ‘danwo


K’o pa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aye yi
Ati gbogbo ifekufe.

4. cr Iwo t’oju Re r’okan mi


Ma wa l’ow’otun mi titi
Ki mna sise lo l’ase Re
Ki nfi ‘se mi gbogbo fun O.

5. mf Je ki nreru Re t’o fuye,


Ki mna sora nigba gbogbo
Ki nma f’oju si nkan t’orun
Ki nsi mura d’ojo ogo.

6 f Ohunkohun t’o fi fun mi


Jeki nle lo fun ogo Re
Ki nf’ayo sure ije mi,
Ki nba O rin titi d’orun.
Amin.
5
L.M.
Nigba wo ni Iwo o to mi wa! OD .101:2.

1 mf Wa s’odo mi, Oluwa mi,


Ni kutukutu owuro,
Mu k’ero rere so jade,
Lat’inu mi s’oke orun.

2 Wa s’odo mi, Oluwa mi,.


Ni wakati osan gangan;
Ki ‘yonu ma ba se mi mo,
K’o si so osan mi d’orun.

3 mpWa s’odo mi, Oluwa mi,


Nigbati ale ba nle lo,
Bi okan mi ba nsako lo,
Mu pada, f’oju ‘re wo mi.

4 Wa s’odo mi, Oluwa mi,


L’oru, nigbati ‘orun ko si,
p Je ki okan aisim mi,
Simi le okan aya Re.

5 mpWa s’odo mi, Oluwa mi,


Ni gbogbo ojo aye mi,.
P Nigbati emi mi ba pin
f Ki nle n’ibugbe l’odo Re
Amin.
6
7.7.7.D.
Sugbon Orun ododo yio la fun enyin ti o beru oruko mi. Matt. 4 : 2.

1. f Krist’s t’ogo Re ka aye,


Krist, Imole, otito; ]
Orun ododo dide,
K’o si bori okunkun,
‘Mole ooro, sunmo mi,
‘Rawo oro yo n’nu mi.

2 mpOoro to de laisi Re,


Ookun on ‘banuje ni,
Ile to mo ko l’ayo,
Bi nko r’oye anu Re,
B’Iwo ko fi ‘mole Re
Kun oju on okan mi.

3 mf Nje be okan mi yi wo,


Le okunkun ese lo,
F’imole orun kun mi,
Si tu aigbagbo mi ka,
Maa f’ara Re han mi si
Titi di ojo pipe
. Amin.
7
S.M.
Li ale, li owuro, ati li osan li emi o ma gbadura. OD. 55 : 17

1. mf Wa s’adura ooro,
Kunle k’agbadura
f Adura ni opa kristian,
Lati b’Olorun rin.

2. mf L’osan, wole labe


Apat’a ayeraye
p Itura ijiji Re dun
Nigba t’orun ba mu.

3 mf Je ki gbogbo ile
Wa gb’adura l’ale:
Ki ile wa di t’Olorun
di Ati ‘bode orun.

4. p Nigba t’o d’oganjo


Je k’a wi l’emi pe,
f Mo sun sugbon okan mi ji
Lati ba O s’ona.
Amin
8
C.M.
Yio fi iye Re bo o. OD. 91:4.

1. mf Imole oro didun yi,


Ji mi ni n’orun mi,
Baba, ife tire nikan
Lo pa omo Re mo.

2. mp Ni gbogbo oni, mo be O
Maa se oluso mi ,
Dariji mi, Jesu mimo
Ki m’ je tire loni.

3. mf Wa se ‘bugbe Re ninu mi,


Emi ore ofe
So mi di mimo l’aye yi,
K’emi le roju Re.
Amin.
9
7.7.7.7.7.3.
Ohun mi ni Iwo o gbo li owuro Oluwa. OD. 5:3.

1 f Jesu, Otun ododo,


Iwo imole ife,
‘Gbati ‘mole owuro,
Ba nt’ila orun tan wa,
Tan ‘mole ododo Re
Yi ka wa

2 mf Gege bi iri nse,


S’ori eweko gbogbo,
K’Emi ore-ofe Re
S’o okan wa di otun,
Ro ojo ibukun Re
p Sori wa.

3 mf B’imole orun ti ntan,


K’imole ife Tire
Si ma gbona l’okan wa,
K’o si mu wa l’ara ya,
K’a le ma f’ayo sin O.
L’aye wa.

4 Amona, ireti wa,


Ma fi wa sile titi,
Fi wa s’abe iso Re
Titi opin emi wa,
Sin wa la ajo wa ja
S’ile wa.

5 Ma to wa l’ona toro
I’ojo aye wa gbogbo
Sin wa la lekun re ja,
Mu wa de ‘le ayo na,
cr k’a le ba won mimo gba
p Isimi,
Amin.
10
6.6.6.6
Gbo ekun mi, Olorun; fiye si adura mi. OD. 61:1.

1. mp Baba mi, gbo t’emi


‘Wo ni Alabo mi,
Ma sun mo mi titi,
Oninu re julo

2. Kristi Oluwa mi
Iye at’ogo mi,
Ki ‘gba naa yara de,
Ti un-ode odo Re

3. p Olutunu julo
‘Wo ti ngbe inu mi
‘Wo t’o mo aini mi,
Fa mi, k’o si gba mi.

4. mf Mimo, mimo, mimo,


Ma fi mi sile lae,
Se mi ni bugbe Re,
Tire nikan laelae.
Amin
11
C.M.
Fi ona re le Oluwa lowo OD. 37:5

1 mf Lekan si, bi orun ti nran,


Awa mbe Olorun
Pe ki ‘mole Re ailopin
S’amona wa loni.

2 f k’a mase da ese da esekese.


K’a ma si ro ibi:
K’a ni otito gan I’enu
Ati ife I’ okan.

3. mf L’ojo oni, Olugbala,


k’a fiiranwo Re
di Lati gba wa lowo esu,
p Ti nd’ ode wa kiri.

4. mf Ki ise wa I’ojojumo
Ma je fun iyin Re.
Be I’O ma mbukun ise wa
S’a mbereninu Re.

5 .cr Je ka fi iwontunwonsi
Ka’wo fekufe wa
Ki’ gberaga nsan ara.
Ma bori Okan wa.

6. f Olorun Baba, at’ Omo


Ati Emi Mimo
Ni kiEda at’ Angeli
F’ogo ailopin fun.
Amin.
12
9.6.9.6
Abrahamu si sunmo odo Oluwa Gen. 13:23.

1 Je ki nsun mo O l’ojojumo,
Jesu Olugbala,
Je ki ngb’ ara le O si, Jesu
Ni gbogbo ona mi.

2 Je ki nfi ewa Re han, Jesu,


Bi orun lor’oke
Je ki ete mi so adun Re,
Pelu ayo toto.

3 Je ki ndabi orisun omi,


Jesu Olugbala,
Ma lo mi lojojumo, Jesu,
Fun ogo Re nikan.

4 Lokan ati l’ero mi, Jesu,


J’oba patapata:
Je ki njeni oloto, Jesu,
Si O l’ohun gbogbo.

5 Mo nk’ ebi at’ onigbe Re, Jesu,


Ebi at’ Okan wa:
Mo nsaferi’ le mi ni Sion:
Nobit’ Olorun wa.
Amin.
13
8.7.11.8.7.11.&Ref.
Olorun si wipe, ki imole ki owa:Imole si wa Gen1:3

1 mf Mole wa I’ afonifoji,
Mole wa I’ Ori oke,
Jesu I’O mu wa s’aye okunkunyi,
Mole wa I’ara itanna
To ndagba I’ eba odo
Imole wa ni ‘bikibi ti mo nlo.
f Mole, Molet’ ife Re orun,
‘ Mole ,mole, li aye wa orun
‘Mole, mole, l’ ona mi gbogbo

2. mf Imole wa loti papa


Ati l’ori koriko,
Nibiti awon eye nkorin iyin:
Imole wa lori oke,
‘Mole wa ni petepele,
Je ki gbogbo eda jumo korin ‘yin.

3. f B’aye tile kun fun ‘ mole


T’o si ntan I’ojojumo,
Okan pupo wa n’nu okunkun sibe
Ti ko gb’oruko Jesu ri,
Tabi ife ‘yanu Re,
Je ki a fi oro Re ran won lowo.
Amin.
14
C.M
Emi dubule, mo si sun: mo si ji Nitiori ti Oluwa ti mi lehin. O.D. 3.3

1. mf Ninu gbogbo ewu oru,


Oluwa I’o so mi:
Awa si tun ri ‘ mole yi
Atun te ekun ba.

2.. Oluwa, pa wa mo I’ oni,


Fi apa Re so wa:
Kiki awon ti ‘wo pamo,
L’o nyo nin u ewu.
3 K’oro wa, ati iwa wa
Wipe, Tire I’awa:
Tobe t’imole otito
Letan I’oju aye.

4. mp Ma je k’a pada lodo Re


Olugbala owon:
Titi a of’oju wa ri
Oju Re li opin.
Amin.
15
6.6.11.D.
A ti tan ife Olorun ko okan wo wa lati odo Emi Mimo wa ti a fi fun wa. Rom. 5:5

1 mf Ife orun sokale,


Tun ka okan mi yi,
Kio si l’ore-ofe Re gbogbo be wo;
f Olutunu orun,
. mf Farahan n’n’ okan mi,
Si mu ki ina mimo Re mu soji.

2 mf Je ko ma jo gere,
ki ‘fekufe d’eru
T’ise iyangbo niwaju afefe;
f Ki ‘mole ologo
mf Tire tan yi mi ka,
Si ona mi ati aye mi gbogbo.

3 mf Fi ife mimo se
Ewu agbada mi;
Ati iwa ‘rele awotele;
f F’okan mimo toto,
mf Ti irele okan,
mpTi nsokun fun ese mi gbogbo, kun mi.

4 mf ‘Gbana okan mi yi
Y’o di alagabara
Lati se ‘fe Re ju b’a ti le ro lo;
f Ko s’eda na t’o mo
Tor’-ofe okan wa
mf Titi y’o fi di ite Emi Mimo.
Amin
16
L.M
Emi o ma fi otito re han lati Irandiran OD.89:1

1 f Baba, a sope ‘toju Re,


T’o f’alafia kun ‘le wa;
Odo Re ni won ti san wa,
Owo Re l’o si ngbe won ro.

2 mf Olorun t’o ye k’a ma yin


L’a nkegbe pe ninu ile wa;
Oluwa orun gbe ile aye.

3 Jek’olukuluku ‘dile
Ma kepe O tosan- toru
K’a ko omo at’om’-odo
L’ofia at’ore-ofe Re.

4 f Beni k’iran ti mbo ma so


T’ola ooko Re t’o logo,
Titi gbogbo wa y’o fi lo
Dapo mo idile t’orun.
Amin.
17
C.M
Ona mi iba je la sile lati ma pa ilana Re mo!. OD.119:5.

1 mf Oluwa, emi y’o korin


Anu at’idajo;
Nigbawon n’Iwo y’o fun mi
N’imole on iye.

2 Mo nfe lati t’ona pipe,


Ki nni okan pipe,
Ona, okan ati ile,
Nibiti Iwo mbe.

3 Mo nfe ki awon oloto


Je oluranwomi;
Ki nfi won s;ore-imule
At’omo-odo mi.

4 cr Ki yo si eke at-etan
Ninu ibugbe mi;
mp Oluwa, jek’ibugbe mi
Ye fun O lati gbe!.
Amin.
18
8.7.8.7

Emi o ma korin anu oluwa lailai OD. 89:1.

1 f L’ojojumo l’a ngbe O ga


Nigbati ti ile ba mo,
T’a ba kunle lati yin O
Fun anu ti owuro.

2 L’ojojumo l’a ngbe O ga


Pel’orin n’ile-eko,
L’ojojumo, pelu iyin,
L’a nse ise wa gbogbo.

3 L’ojojumo l’a ngbe O ga


Ninu orin k’a to sun
Awon angel’ gbo, won si nso
Awon agutan Kristi.

4 L’ojojumo l’a ngbe O ga


Ki se ni iyin lasan
Otito ati igboran
Nf’ogo Re han ninu wa.

5 mf L’ojojumo l’a ngbe O ga


Gba t’a ngbiyanju fun Krist’
Lati ma farada iya
K’a pa ese run n’nu wa.

6 f L’ojojumo l’a nbe O ga


Tit’ojo wa y’o fi pin,
T’ ao simi n’nu lala gbogbo,
L’alafia d’ojo Re
Amin.
19
L.M

Nigbati iwo ba sun, yio ma so O . Owe 6:22.

1 f Ogo f’Olorun l’ale yi


Fun gbogbo ore imole,
So mi, Oba awon Oba
L’abe ojiji iye Re.

2 mp Oluwa f’ese mi ji mi,


Nitori omo Re, loni
K’emi le wa l’alafia,
Pelu Iwo ati aye.

3 mf Je k’okan mi le sun le O,
K’orun didun p’oju mi de
Orun ti y’ o m’ara mi le,
Ki nle sin O li owuro .

4 mp Bi mo ba dubule laisun,
F’ero orun kun okan mi,
Ma je ki nl’ala buburu,
Ma je k’ipa okun bo mi.

5 ff Yin Olorun, ibu ore;


E yin, eyin eda aye,
E yin, eyin eda orun,
Yin Baba, Omo on Emi
Amin.
20
6.4.6.6.
Je ki adura mi ki o wa si iwaju Re bi ebo asale: OD. 141:2.

1 . mf Orun fere wo na,


Ojo lo tan,.
cr K’ife k’o ji dide
K’o rubop aseale.

2. pp Ili Jesu l’origi,


Ti teriba,
T’O jowo emi Re
Le Baba Re lowo.

3 mf Be ni mo f’emi mi
Fun l’a fun tan,
Ni’pamo gbogbo sa wa.

4 mf Nje emi o simi


L’odo Re je,
Laije k’ero kan so
Yo okan mi lenu.

5 ‘Fe Tire ni sise,


L’onakana;
Mo d’oku s’ara mi
Ati s’ohun gbogbo.

6 mf Be l’emi ye; sugbon


Emi ko, On
Ni mbe laye n’nu mi,
L’agbara ife Rer.

7 f Metalokan Mimo
Olorun kan,
Lae ki nsa je Tie
K’on je t’emi titi
. Amin,
21
8.7.8.7.7.7.
Eni ti npa o mo ki yio togbe OD.121:3

1 f Ife Re da wa si loni,
Lare, a si dubule,
Ma so wa ni ‘dake or,
K’ota ma yo wa l’enu,
Jesu, se Olutoju wa;
Iwo l’o dun gbekele.

2 Ero at’alejo l’aye,


A ngb’arin awon ota,
Yo wa, at’ile wa l’ewu;
Lapa Re ni ka sun si;
p N’ijo iyonu aye pin:
K’a le simi l’odo Re
. Amin.
22
10.10.10.10.
Ita wu duro: nitori o di ojoo ale. Lk.24:29.

1 mf Wa ba mi gbe, ale fere le tan;


Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe:
Bi oluranlowo miran ba ye,
lranlowo alaini, wa ba mi gbe.

2 p Ojo aye mi nsere lo s’opin,


Ayo aye nku, ogo re nwomi,
Ayida at’ibaje ni mo n ri,
cr ‘Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe.

3 mp Ma wa l’eru b’Oba awon oba,


B’oninure, wa pelu ‘wosan Re,
Ki O si ma kanu fun egbe mi,
Wa, Ore elese, wa ba mi gbe.

4 Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo,


Kilo le segun esu b’ore Re?
Tal’o le se amona mi bi Re?
N’nu ‘banuje at’ayo ba mi gbe.

5 mf Pelu ‘bukun Re, eru ko ba mi


Ibi ko wuwo, ekun ko koro,
f Oro iku da? ‘segun isa da?
Un o segun sibe, b’Iwo ba mi gbe.

6. p Wa ba mi gbe, ni wakati iku,


cr Se ‘mole mi, si toka si orun
f B’aye ti nkoja, k’ile orun mo,
f.p.mp Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe
. Amin
23
L.M.
Emi o dubule pelu li alafia, emi o si sun. OD. 4:8

1. mf Iwo Imole okan mi,


Ni odo Re, oru ko si,
Ki kuku aye ma bo O,
Kuro l’oju iranse Re.

2. pp Ni gba t’orun ale didun


Ba npa ipenpe ‘ju mi de,
K’ero mi je lati simi,
Lae l’aya Olugbala mi.

3. mf Ba mi gbe l’oro tit’ale,


Laisi Re, emi ko le wa,
Ba mi gbe ‘gbat’ile ba nsu,
Laisi Re, emi ko le ku.

4. mp Bi otosi omo Re kan


Ba tapa s’oro Re loni,
cr Oluwa, sise ore Re,
Ma je k’osun ninu ese.

5. mf Bukun fun awon alaisan,


Pese fun awon talaka,
di K’orun onirobinuje
pp Dabi orun omo titun.

6. cr sure fun wa ni gbat’aji,


Ka to m’ohun aye yi se
f Titi awa o de b’ife
T’a o si de Ijoba Re.
Amin
24
L.M.
Nigbati o di asale, nwon ko gbogbo awon alaisan to o wa. Mk. 1:32.

1. mf L’oju ale ‘gbat’orun wo


Won gbe abirun w’odo re
p Oniruru ni aisan won
f Sugbon won f’ayo lo ‘le won.

2. mf Jesu, a de l’o j’ale yi,


A sun m’O t’awa t’arun wa,
cr Bi a ko tile le ri O,
Sugbon, a mo p’o sun mo wa.

3. mp Olugbala, wo osi wa,


Opo nsaisan, opo nk’edun
Opo ko ni ‘fe si O to,
Opo ni ‘fe won si tutu.

4. Opo ti ri p’asan l’aye


Sibe nwon ko f’aye sile,
Opo l’ore ba n’inu je,
Sibe won ko fi O s’ore.

5. Ko s’okan ninu wa t’o pe


Gbogbo wa si ni elese
Awon t’o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe.

6. mf Sugbon Jesu, olugbala,


Eni bi awa ni ‘wo ‘se
‘Wo ti ri ‘danwo bi awa
‘Wo si ti mo ailera wa.

7. Agbar’owo Re wa sibe
Ore re si ni agbara
p Gbo adura ale wa yi
cr Ni anu, wo gbogbo wa san.
Amin
25
10.10.10.10
Emi o dide, emi o si to baba mi lo. Lk. 15:18.

1. mp Baba, a tun pade l’oko Jesu,


A si wa teriba lab’ese Re,
A tun fe gb’ohun wa s’oke si O
Lati wa anu, lati korin ‘yin.

2. f A yin O fun itoju ‘gba gbogbo


Ojojumo l’a o ma rohin ‘se Re
Wiwa laye wa, anu Re ha ko
Apa Re ki O fi ngba ‘ni mora.

3. p O se! a ko ye fun ife nla Re,


A sako kuro lodo Re poju,
mf Sugbon kikankikan ni o si npe
Nje a de a pada wa ‘le Baba.

4. mp Nipa ooko t’o b’or’ohun gbogbo


Nipa ife t’o ta ‘fe gbogbo yo,
Nipa eje ti a ta fun ese,
mp Baba, a tun pade l’oko Jesu
A si wa teriba lab’ese Re,
A tun fe gb’ohun wa s’oke si O
Lati wa anu, lati korin ‘yin

2. f A yin O fun itoju ‘gba gbogbo


Ojojumo l’ao ma rohin ‘se Re
Wiwa laye wa, anu Re ha ko
Apa Re ki O fi ngba ‘ni mora

3. p O se! a ko ye fun ife nla Re


A sako kuro lodo Re poju,
mf Sugbon kikankikan ni o si npe
Nje a de a pada wa ‘le Baba.

4. mp Nipa ooko t’o b’or’ohun gbogbo


Nipa eje ti a ta fun ese,
cr Silekun anu, si gba ‘ni sile
. Amin.
26
10.4.10.4.10.10.
Li osan pelu, o fi awosanmo se amona won, ati li oru gbogbo pelu imole ina. OD.
78:14

1. mp‘Wo Imole larin okun aye,


Ma sin mi lo;
Okunkun su, mo si jinna s’ile,
Ma sin mi lo;
cr Nko s’aferi ola bi y’o ti ri,
To ese mi, ‘sise kan to fun mi.

2. p Nigba kan ri, emi ko be O pe


K’O sin mi lo;
Beni nko fe O, sugbon nigba yi,
Ma sin mi lo;
Afe aye ni mo si nto leyin,
Sugbon Jesu, ma ranti igba ni.

3. mf Ipa Re l’o ti ndi mi mu, y’o si


Ma sin mi lo,
Ninu ere ati yangi aye,
Ma sin mi lo;
Titi em’o fi ri awon wonni
Ti mo fe, ti won ti f’aye sile.
Amin
27
8.7.8.7.
Kiyesi, eniti npa Israeli mo, ki I togbe, beni ki I sun. OD. 121:4

1. mp K’ato sun, Olugbala wa,


Fun wa n’ibukun ale,
A jewo ese wa fun O,
Iwo l’O le gba wa la.

2. cr B’ile tile ti su dudu,


O kun ko le se wa mo,
mf I wo Eniti ki ‘sare,
Nso awon eniyan Re.

3. p B’iparun tile yi wa ka,


Ti ofa nfo wa koja,
mf Awon Angeli yi wa ka,
p Awa o wa lailewu.

4. p Ma ko wa, ma fi wa sile,
K’agbara wa di otun,
Ki imole oro ji wa,
K’a le ma fe ise Re.

5. N’irele awa fara wa,


S’abe abo Re, Baba,
Jesu, ‘Wo t’O sun bi awa,
Se orun wa bi tire.

6. Emi mimo, rado bo wa,


Tan ‘mole s’okunkun wa,
cr Tit’awa o fi ri ojo,
f Imole ayeraye. Amin.
28
8.8.8.D.
Nitori Oluwa yio je imole ainipekun fun o. Isa. 60:20.

1. mf Jesu, bukun wa k’a to lo,


Gbin oro Re si wa l’okan;
K’o si mu k’ife gbigbona
Kun okan ilowowo wa.
cr Nigba yiye at’iku wa,
p Jesu jare, se ‘mole wa.

2. mp Ile ti su, orun ti wo


‘Wo si ti siro iwa wa
Die nisegun wa loni,
Isubu wa lo p’apoju.

3. mf Jesu, dariji wa, fun wa


L’ayo ati eru mimo
At’okan ti ko l’abawon,
K’a ba le jo O l’ajo tan.

4. mp Lala dun, tori ‘Wo se ri;


Aniyan fere, O se ri,
Ma je k’a gbo t’ara nikan,
K’a ma bo sinu idewo.

5. mp A mbe O f’awon alaini,


F’elese at’awon t’a fe,
Je ki anu Re mu wa yo,
‘Wo Jesu l’ohun gbogbo wa.

6. mf Jesu bukun wa, ile su,


Tikara Re, wa ba wa gbe,
Angel’ rere nso ile wa,
A tun f’ojo kan sunmo O
. Amin.
29
9.8.9.8.
Ati lati duro li oro owuro lati dupe, ati lati yin Oluwa, ati be gege li asale. I Kro. 23:30.

1. mf Oluwa, ojo to fun wa pin,


Okunkun si de l’ase Re,
‘Wo l’a korin owuro wa si,
Iyin Re y’o m’ale wa dun.

2. mf A dupe ti Ijo Re ko sun,


B’aye ti nyi lo s’imole,
O si nsona ni gbogbo aye,
Ko si simi t’osan-t’oru.

3. B’ile si ti nmo l’ojojumo,


Ni orile at’ekusu,
Ohun adura ko dake ri,
Be l’orin iyin ko dekun.

4. Orun t’o wo fun wa, si ti la,


S’awon eda iwo-orun,
Nigbakugba ni enu si nso
Ise ‘yanu Re di mimo.

5. cr Be, Oluwa, lae n’Ijoba Re,


Ko dabi ijoba aye;
f O duro, o si nse akoso,
Tit’eda Re o juba Re
. Amin.
30
7.6.7.6.8.8
Nitori ojo nlo.Jer. 6:4.

1. Ojo oni koja lo,


A dupe, Oluwa,
Jo, gba wa lowo ese
Ni wakati oru,
di Jesu jo, f’iso Re so wa,
cr Si mu wa la oru yi ja.

2. mf Ayo oni koja lo,


A gb’okan wa s’oke
Jo, ma je k’a n’ikose
Ni wakati oru;
di Jesu, jo fun wa n’imole,
cr Si mu wa la oru yi ja.

3. mf Lala oni koja lo,


A fi orin yin O,
Jo, ma je k’a ri ewu
Ni wakati oru;
di Jesu, jo f’iso Re so wa,
cr Si mu wa la oru yi ja.

4. mf S’Olupamo wa, Baba,


Nitori ‘Wo l’O mo
Gege b’ewu ti po to,
Ti a o ba pade;
di Jesu, Olufe, gbo ti wa,
cr Si mu wa la gbogbo won ja.
Amin.
31
8.8.8.4.
Orun ki yio pa o nigba osan, tabi osupa nigba oru.OD. 121:6.

1. mf Oro didan ti rekoja;


Wawa l’akoko na fo lo,
di Bi osan si ti nkoja lo,
Nile nsu bo.

2. mf Kukuru, l’ojo aye wa,


Were l’osan re nde opin;
Krist’, ‘Wo ti se Ona Iye,
Sin wa de ‘le.

3. cr Jo fi ore-ofe Re nla
Gbe okan wa b’ilu t’orun;
Je k’a ma wo ‘le didan ni
Ti mbe l’oke.

4. f Nibi ‘mole, iye, ayo


At’alafia gbe njoba,
T’awon angel’ ko dekun ‘ko
Orin iyin.

5. f T’awon mimo wo ‘so ala,


Ti okunkun ale ki su,
Ti ‘Wo ‘Mole ayeraye
Je Oluwa.
Amin.
32
8.3.3.6.
Emi o ma yin O tinu-tinu mi gbogbo. OD. 138:1.

1. mp Ki nto sun, fun ore t’oni


T’Olorun
Se fun mi
cr Un o yin Olugbala

2. mfOluwa, kini un o fi yin


Oko Re
T’okun fun
Anu ati ore.

3. ‘Wo si gba ise mi.


L’ona Re
di ‘Wo gb’ ebe’
‘Wo si gba ise mi,

4. mp Ma ko mi, ma fe mi titi
F’alafia
Re fun mi,
Titi ‘wo y’o pe mi

5. mf ‘Wo apata at’odi mi,


F’ipa Re
Pa mi mo
‘Gba m’ba dubule sun.

6. p Nigbakugba ti mo ba ku,
cr Je k’emi
Ji dide
f Pelu awon mimo
. Amin
33
7.7.7.7.7.7.
Iwo o pa a mo li alafia pipe, okan eniti o simi le O. Isa. 26:3.

1. mf L’alafia l’Olorun
Sin wa ja ose miran;
E je k’a bere ‘bukun
L’ojo ‘simi ti mbo yi,
Ojo t’o tobi julo,
Apere ayeraye.

2. f K’a sope opo aanu


Ti a ri gba l’ose yi;
Olodumare so wa, O bo wa, O si to wa
di B’a ti s’alaimore to,
T’a nfi ese s’esan fun

3 mp B’a ti ntoro ifiji


L’oruko Olugbala,
Fi oju anu Re han, Le ese on ‘tiju lo,
Gba wa lowo aniyan,
K’a le sun l’alafia.

4 mf ‘Gbati ile ba si mo,


Je k’a mo p’O wa n’tosi
Je k’a le ri ogo Re,
‘Gbati a ba de ile Re,
cr Nibe, Oluwa fun wa
N’itoju ase orun.

5 mf Jek’iro ‘ihinrere Re
Gb’elese at’oloto;
cr k’eso or’ofe ma po,
K’o tan gbogbo arun wa,
f K’ojo ‘simi ma ri be
Tit’ao de ijo t’orun.
Amin.
34
7.7.7.7.4. & Ref.
Emi o gbe e leke, nitori ti o mo oruko mi.OD. 91:14

1. mf Orun ti de iwo re,


‘Simi ni’orun bo w’aye;
Wa ka josin bi ale
Ti ntan ‘na fitila re
Loju sanma.
mp Mimo mimo, mimo Oba ogo
Torun-taye kun fun O,
f Torun-taye l’o yin O, Oga Ogo.

2. mp Oluwa Iye, labe


Orun ti se ‘bugbe Re,
Ko awa ti nw’oju Re
Jo sin’agbo ife Re;
‘Wo mbe n’tosi.

3. Bi ile si ti nsu lo,


‘Wo t’o f’ife d’aye mu
L’okan wa nwa, rekoja
Ogo at’ewa ‘rawo
T’o boju Re.

4. mf Gba irawo at’osan,


At’oru ki o si mo,
Oluwa awon angel’,
Je kari ‘mole aye
Ki okun pin.
Amin.
35
7.7.7.7
Iwo ti ngbo adura, si odo re ni gbogbo eniyan mbo. OD. 65:2.

1. mf Agboju s’oke si O,
At’owo ati okan;
Tewogba adura wa,
p B’o tile se ailera.

2. Oluwa je k’a mo O.
Je k’a mo oruko Re;
Je k’awa se ife Re,
Bi won ti nse li orun.

3. mp Nigbati a sun l’oru,


So wa k’o duro ti wa;
f Nigbati ile si mo,
ff K’a ji, k’a fi ‘yin fun O
.Amin.
36
6.5.6.5
Jesu si duro larin, O ni, “Alafia fun nyin” Jn. 20:26.

1. mf Jesu wa s’arin wa,


L’agbar’ajinde,
Je k’isin wa nihin
Je isin owo.

2. mp Mi Emi Mimo Re
Sinu okan wa,
cr Mu ‘foya at’aro
Kuro lokan wa.

3. f Bi a ti nyara lo,
L’ona ajo wa,
K’a ma sona f’oro
T’ojayeraye.
Amin.
37
13.10.13.10
E ma a sin Oluwa ninu ewa iwa mimo OD. 96:9.

1. mf E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo,


Wole fun k’e si pokik’ogo Re
Pelu wura ‘gboran ati turari ‘rele,
E wole fun Un k’e si juba Re.

2. Gbe eru aniyan yin lele lese Re,


Y’o si ti ka Re ba yin gbe d’ori;
Y’o tu o ninu, yo si gbo adura re,
Y’o to ‘sise re bo ti to fun o.

3. Ma beru lati wo agbala Re, pelu


Kiun ninu oro t’o le pe n’tire;
cr Ewa otito ati ife owuro,
f Ebo wonyi la nbere lowo re.

4. mf B’atile m’awon wonyi wa ni’wariri


cr On y’o gba won l’oruko to sowon,
f Ayo owuro y’o dipo ekun ale
Ireti kikun y’o dipo eru.

5. mf E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo,


Wole fun k’e si pokik’ogo Re
Pelu wura ‘gboran ati turari ‘rele,
E wole fun Un ke si juba Re.
Amin.
38
C.M.
E wa, e je ki a korin si Oluwa.OD. 95:1

1. mf E wa k’a korin s’Oluwa,


Olukuluku wa;
f Ki a ho iho ayo si
Apata ‘gbala wa.

2. E je k’a wa siwaju Re
Pelu ‘yin at’ope;
Ka ko orin pel’ore ofe,
Ka si yo ayo nla.

3. ff Olorun yi tobi l’Oba


J’awon orisa lo;
Gbogb’aye wa nikawo Re
At’awon oke nla.

4. f Tire li awon okun nla,


On ni O si da won;
Ati ‘yangbe ile pelu,
Owo Re lo si da.

5. mf E wa, e je ki a wole
Ki a teriba fun,
Ki a si kunle niwaju
Oluwa Eleda.
Amin.
39
S.M.8 Refrain
Eniti enyin fe lairi.I Pet. 1:8

1. f E yin te fe Oluwa,
E fi ayo yin han,
E jumo Ko orin didun,
E jumo ko orin didun,
K’e si y’ite na ka,
K’e si y’ite na ka.
ff A nyan lo si Sion’,
Sion’ to l’ewa julo
A nyan goke lo si Sion’,
Ilu Olorun wa l’ewa.

2. f Je k’awon ni ma korin
Ti ko m’Olorun wa
Sugbon awon omo Oba,
Sugbon awon omo Oba
Y’o royin ayo won,
Y’o royin ayo won.

3. Oke Sion’ l’o nmu


Egberun adun wa
Ki a to de gbangba orun
Ki a to de gbangba orun
Pelu ‘ta wura re,
Pelu ‘ta wura re.

4. mf Nje ka ma korin lo,


cr K’omije gbogbo gbe
f A nyan n’ile Imanuel’
A nyan n’ile Imanuel’.
ff S’aye didan loke,
S’aye didan loke.
Amin.
40
D.S.M
Eniti enyin fe lairi. 1 Pet. 1:8

1. f E yin t’e f’Oluwa,


E fi ayo yin han;
E jumo ko orin didun
B’e ti ny’ite Re ka;
Jek’awon ‘ni dake,
Ti ko m’Olorun wa;
Sugbon k’awon ‘ranse oba
Ma ro ayo won ka.

2. Olorun t’o joba,


Ti nwo gbogbo aye
Ti ngun awosanmo l’esin
Ti nmu ‘ji pa roro;
ff Tiwa l’Olorun yi
Baba Olufe wa;
Y’o ran agbara t’orun wa
Lati gbe wa soke.

3. mf Nibe l’ao r’oju Re.


T’a ki o dese mo;
T’ao si ma jadun ailopin,
Nipa or’ofe Re:
cr Loto, k’a to jinde
Si iye ailopin,
Ero irora nlanla na
f Nmu ayo wa bi si.

4. Eni-or’ofe ri
‘Bere ogo laye;
Eso orun ngberu laye
N’nu gbagbo on ‘reti:
cr Nje k’orin wa goke,
K’omije gbogbo gbe;
f A nkoja lo n’ile ‘Manuel’
S’aye rere loke.
Amin
41
13.9.13.9. & Ref
E ma ba ara nyin soro ninu Psalmu, ati orin iyi ati orin Emi. Efe. 5:19.

1. mf Ko su wa lati ma ko orin ti igbani


f Ogo f’Olorun Aleluya!
A le fi igbagbo korin na s’oke kikan.
ff Ogo f’Olorun, Aleluya!
mf Omo Olorun ni eto lati ma bu s’ayo
Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns’aferi Re;
Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,
f ‘Ogo f’’Olorun, Aleluya!

2. mf Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada,


f Ogo f’Olorun Aleluya!
mf Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun;
f Ogo f’Olorun, Aleluya!

3. mf Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,


f Ogo f’Olorun Aleluya!
Nibiti ao ri Oba ogo n’nu ewa Re,
ff Ogo f’Olorun, Aleluya!

4. mf Nibe ao korin titun t’anu t’O da wa nde,


f Ogo f’Olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin ‘yin ti Krist;
ff Ogo f’Olorun, Aleluya!

Amin.
42
C.M.

Eyi li Ojo ti Oluwa da OD. 118:24.

1. mf Wa, je k’a jumo f’ohun kan


Korin yi Ite ka:
Oni l’ojo t’Oluwa da
T’o si pe ni Tire.

2. f Ojo yi l’Olorun bukun.


Larin ojo meje;
Apere ‘simi ailopin
T’awon t’orun ngbadun.

3. Nje k’a ma korin oko Re


K’a ma reti ojo
T’Oludande y’o sokale
T’asan aye y’o pin.

4. Lojojumo titi aye


Ni ki a ma korin;
K’a ma yo ninu Oluwa
Titi ayeraye. Amin.
43
L.M.

Oluwa yio fun ni li ore-ofe ati ogo: ko si ohun rere ti yio fa sehin lowo awon ti nrin dede.
OD. 84:11.

1. mp Oluwa gbo adura wa


N’nu le Re l’ojo mimo yi;
Bi ebo ope ni ile yi
K’orin wa je itewogba.

2. cr Oluwa, isimi Re dun:


Sugbon t’oke ju t’aye lo;
Sibe pelu ‘reti ayo
Li okan ongbe wa nsare:

3 . mf Ko si are, ko si ise,
Ese, iku ki y’o de ‘be,
Ohun irora ki y’o dun
Nibiti ahon aiku wa.

4. f Ko si idagiri ota,
Isimi laisi aniyan,
Oju ojo ko su nibe,
Osan gangan ayeraye.

5. mf Bere, ojo t’a ti nreti,


Mo si aye irora yi,
Ao f’ayo rin l’ona t’ayo
Ao si sun ninu Oluwa.
Amin.
44
7.6.7.6.D.
Mo wa ninu emi li ojo Oluwa.Ifi. 1:10.

1. f Ojo ‘simi at’ayo


Ojo inu didun,
Itunu fun ‘banuje
Ojo dida julo,
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re,
p Nko Mimo, Mimo, Mimo,
S’Eni Metalokan.

2. f L’ojo yi n’imole la,


Nigba dida aye
Ati fun igbala wa,
Krist’ jinde n’nu oku
mf L’ojo yi li Oluwa
Ran Emi t’orun wa,
Ojo ologo julo
T’a tan ‘mole pipe.

3. mf Ebute abo ni O
Larin iji aye;
Ogba didara ni O
Nib’omi iye nsan
Orisun ‘tura ni O
Laye aginju yi;
Lori re, bi ni Pisga
L’a now ‘le ileri.

4. mp L’oni s’ilu t’are mu


Ni manna, orun nbo
Si ipejopo mimo
N’ipe fadaka ndun,
N’ibiti ihinrere
Ntan imole mimo
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara.

5. Ka r’ore-ofe titun
L’ojo ‘simi wa yi
K’a si de ‘simi t’o ku
F’awon alabukun,
Nibe k’a gb’ohun soke
Si Baba at’Omo;
Ati si Emi Mimo
N’iyin Metalokan.
Amin.
45
L.M.
Nitori omo eniyan je Oluwa ojo isimi.Mat. 12:8.

1. f Oluwa ojo simi


Gbo eje wa nihin, loni,
Gba orin iyin ti a nko
Bi ebo ope wa si O.

2. A fe isimi t’aye yi
Sugbon ‘simi t’orun dun ju
Eyi ni l’okan wa nle pa;
Pelu itara on ife.

3. mf Ko saare mo tab’iponju
Ese tab’egbe kio de ‘be;
Ose ki y’o dapo merin
Ti awon eni aiku nko.

4. Ko si idagiri ota,
Beni ko s’ipaya nibe;
Ko si oru, ko s’ikuku;
mf Afi osan titi laelae.

5. Bere, ojo t’a ti nreti,


Afemoju re l’a fe ri,
A fe yo! Lona ise yi
K’a si de ibi ‘simi na
. Amin.
46
6.6.6.6. D
Oni li ojo isimi fun Oluwa. Eks. 16:25.

1. mf Jesu, a fe pade
L’ojo Re mimo yi,
mf A si y’ite Re ka
L’ojo Re mimo yi
ff Wo ore wa orun,
Adura wa mbo wa,
mf Bojuwo emi wa
L’ojo Re mimo yi.

2. f Ako gbodo lora


L’ojo Re mimo yi,
Li eru a kunle
L’ojo Re mimo yi
Ma to gbogb’ero wa,
K’Iwo k’o si ko wa
K’a sin O b’o ti ye
L’ojo Re mimo yi,

3 . A teti s’oro Re
L’ojo Re mimo yi,
Bukun oro t’a gbo
L’ojo Re mimo yi.
ff Ba wa lo ‘gba t’a lo,
F’ore igbala Re
Si aya wa gbogbo
L’ojo Re mimo yi.
Amin.
47
L.M.
Oluwa busi ojo meje, O si ya si mimo.Eks. 20:11.

1. f Ojo mefa t’ise koja


Okan t’isimi si bere,
Wa, okan mi si ‘simi re,
Yo s’ojo t’Olorun busi.

2. f Olorun, a yo si ‘se Re,


L’oniruru t’ogbo t’otun;
A fi ‘yin ro anu t’o lo,
A ni ‘reti s’eyi ti mbo.

3. Ki ‘ronu at’ope wa nde


Bi ebo turari s’orun,
K’o le fa inu didun wa
T’o je teni t’o mo nikan.

4. Ibale aya orun yi,


L’eri isimi t’o logo;
T’o wa fun eniyan mimo,
p Opin aniyan at’aisan.
Amin.
48
C.M.

Eyi li ojo ti Oluwa da; awa o ma yo, inu wa yo si ma dun ninu re. OD. 118:24.

1. f Eyi l’ojo t’Oluwa da,


O pe ‘gba na n’ti Re;
K’orun k’o yo, k’aye ko yo
K’iyin yi ‘te na ka.

2. Loni O jinde n’nu oku,


Ijoba Satan ‘tu,
‘Won mimo tan ‘segun Re ka
Won ns’oro ‘yanu Re.

3. ff Hosana si Oba t’a yan


S’omo mimo Dafid’;
mf Oluwa, jo sokale wa
T’Iwo t’igbala Re.

4. Abukun l’Oluwa t’o wa


N’ise, ore-ofe
T’o wa l’oruko Baba Re,
Lati gba ‘ran wa la.

5. ff Hosana li ohun goro,


L’orin Ijo t’aye,
Orin t’oke orun l’ohun,
Yi o dun ju be lo.

Amin.
49
L.M.
Nitori Iwo, Oluwa li o ti mu mi yo nipa ise re. OD. 92:4

1. f Didun ni ‘se na, Oba mi,


Lati ma yin oruko Re,
Lati se ‘fe Re l’owuro
Lati so oto Re l’ale.

2. p Didun l’ojo ‘simi mimo,


Lala ko si fun mi l’oni,
Okan mi ‘ba le ma korin
Bi ohun duru Dafidi!

3. f Okan mi o yo n’Oluwa,
Y’o yin ise at’oro Re
Ise ore Re ti po to!
Ijinle si ni imo Re.

4. mf Emi o yan ipo ola


‘Gb’ore ofe ba we mi nu,
Ti ayo pupo si ba mi
Ayo mimo lat’oke wa.

5. f ‘Gbana un o ri, un o gbo, un o mo


Ohun gbogbo ti mo ti nfe;
Gbogbo ipa mi y’o dalu
Lati se ife Re titi.
Amin.
50
7.7.7.7
Nitorina, isimi kan ku fun awon eniyan Olorun. Heb. 4:9

1. mf K’ojo ‘simi yi to tan,


K’a to lo f’ara le le,
cr Awa wole lese Re,
di A nkorin iyin si O.

2. mf Fun anu ojo oni,


Fun isimi l’ona wa,
f ‘Wo nikan l’a f’ope fun,
Oluwa at’Oba wa.

3. p Isin wa ko nilari,
Adura wa lu m’ese,
Sugbon ‘Wo l’o nf’ese ji
Or’-ofe Re to fun wa.

4. mf Je k’ife Re ma to wa,
B’a ti nrin ‘nu aye yi,
mp Nigbat’ajo wa ba pin,
K’a le simi l’odo Re.

5. f K’ojo ‘simi wonyi je


Ibere ayo orun,
B’a ti nrin ajo wa lo
Si ‘simi ti ko lopin.
Amin.
51
S.M.
Yio si dabi imole oro nigbati orun ba la ati ti ko ni kuku. II Sam. 23:4

1. f O jo mole l’eyi
mf Ki ‘mole wa loni,
cr ‘Wo orun ran s’okunkun wa,
K’o si le oru lo.

2. p Ojo ‘simi l’eyi


mf S’agbara wa d’otun:
di S’ori aibale aya wa
mp Se ‘ri itura Re.

3. p Ojo alafia,
mf F’alafia fun wa:
cr Da iyapa gbogbo duro,
Si mu ija kuro.

4. p Ojo adura ni:


mf K’aye sunmo orun:
cr Gb’okan wa s’oke sodo Re,
Si pade wa nihin.

5. f Oba ojo l’eyi;


mf Fun wa ni isoji;
ff Ji oku okan wa s’ife;
‘Wo asegun iku.
Amin.
52
S.M.

Emi o si bere lowo Baba, oun o si fun yin li Olutunu miran, ki o le ma ba yin gbe titi
laelae. Jn. 14:16.

1 . f Emi wa ba wa pe,
L’ojo isimi yi;
Laisi Re awa ko le sin,
A ko le gb’adura.

2. f Asan li orin wa,


Iwasu wa asan,
Ipejopo wa ko l’ere
Afi b’O pelu wa.

3 . f Ojise Orun nla,


Tani mo je bi Re?
Tikalare wasu fun wa
Nipa iranse Re.

4. f Wa ko wa lati be,
L’ohun t’a ba toro;
Si mu ‘bere wa to Jesu
T’a be l’oruko Re.

5. mf Nipa ‘ranlowo Re
L’a n’ireti anu,
Isin wa ko le sai l’ere
B’Iwo ba pelu wa.

Amin.
53
C.M.
Mo wa ninu emi li ojo Oluwa.Ifi. 1:10

1. f Je k’a yin Oluwa ‘simi


Pelu awon mimo,
Ti nf’ayo at’orin didun
Lo ‘simi ailopin.

2. mf Oluwa, b’ati nranti Re


N’ibukun wa npo si:
Nipa orin iyin l’ a nko
B’a ti y’ ayo’ segun.

3. Lojo ayo yil’ Olorun,


Oro ayeraye,
F’ise nla han , t’o logo ju
Ti iseda aye.

4. f O jinde, eni f’irora


di Ra gbogb’ eda pada:
Ise nla ni dida aye,
p Idande ju yi lo.
Amin.
54
C.M
Ranti Ojo isimi, lati ya a simimo. Eks, 20:8

1. f B’o o ti dun to l’oj’ owo yi,


Ojo t’ o dara ju,
Ki a pa’ ronu aye ti,
Ki a pa ‘ ronu aye ti,
K’a ronu nkan t’ orun!

2. mf B’o ti dun to lati l’ aye


Bebe fun ‘ dariji!
K’a fun igboya omo pe,
‘Baba ti mbe l’ orun’

3. Lati gb’ or’ alafia didun


Lat’ enu ranse Re:
P Lati mu k’ a sokun ese
K’a ri ona orun.

4. p B’o ba si je pe o ti wa
Lati le ese lo,
Eni t’ o n wo inu okan,
Y’ o ran or’ ofe wa.

5. f Nje ma wole ojo owo


Ojo t’ o dara ju,
T’ okan pe lati san eje
Im’ore fun orun
Amin.
55
S.M
Ranti ojo isimi , lati ya a simimo. Eks. 20:8

1. f Olorun wa Orun,
T’o fi ojo mefa
Da nkan gbogbo ti mbe laye
Simi n’ijo keje.

2. f O pase k’ a bowo
Fun ojo isimi,
Ibinu Re tobi pupo
S’ awon t’ o rufin yi.

3. Awon baba nla wa,


f Ti ku nin okunkun:
Won je ogbo aborisa
Won ko mo ofin Re.

4. mf Awa de Oluwa,
Gege bi ase Re:
Leyin ise ijo mefa,
Lati se ife Re.

5. mf Mimo l’ojo oni,


O ye ki a simi,
K’a pejo ninu ile Re:
K’ a gbo ro’ mimo Re.

6. Isimi nla kan ku


F’awon eniyan Re:
Om’ Olorun, Alabkun
Mu wa de’ simi Re
Amin.
56
8.7.8.7. D.
Mo si gbo bi enipe ohun opolopo eniyan, ati bi iro omi pupo, ati bi iro ati nlanla, nwipe,
Aleluya nitori Oluwa olorun wa Olodunmare njoba.
If. 19:6

1. f Gbogb’ ogun orun nro keke,


Angeli mu harpu won,
Awon mimo nt’ ohun won se,
Lati josin t’o l’ogo:
Ojo ‘simi t’Olorun de
Ojo t’o l’ ogo julo,
Orun kun fun iho ayo
A!b isin won ti dun to,

2. f Jek’ a pelu awon t’orun,


Yin Olrun oba wa:
Jek’ a pa’ le okan wa mo,
K’af’ohun mimo korin
Apere ni ti won li je
T’isimi ti won loke
Titi ao fi ri Oluwa
Ti a nsin l’ojukoju.

3. mf K’o to d’ igba na e, jeki


Ama sin l’ ojo keje,
K’a f’aniyan wa s’ apakan
K’ a pe sinu ile Re:
O ti pase k’a ma se be,
Y’o bukun ipejo wa,
Eje k’a sin liaisare
Ere re y’o je tiwa.
Amin
57
C.M.
Inu mi dun nigbati won wi fun mi pe, E je ka lo sile Oluwa. OD. 122:1

1. f Bi mo ti yo lati gb’oro
tenu awon ore;
Pe, “Ni Sion’ ni k’a pe si
K’a p’ojo mimo mo.”

2. f Mo f’onata at’ekun re;


Ile t’a se loso,
Ile t’a ko fun Olorun;
Lati fi anu han.

3. S’agbala ile ayo na,


L’eya mimo si lo,
Omo Dafid’ wa lor’ite,
O nda ejo nibe.

4. O gbo iyin at’igbe wa;


B’ohun eru re
mp Ti nya elese sib’egbe,
A nyo ni wariri.

5. K’ibukun pelu ibe na]


Ayo nigbakugba;
K’a fi ore ati ore,
F’awon ti nsin nibe.

6. Okan mi bebe fun Sion’


Nigbati emi wa;
f Nibe ni ‘batan at’ore
At’Olugbala wa
. Amin.
58
L.M.
Awon ni emi o si mu wa si oke mimo mi, emi o si mu inu won dun, ninu ile adua mi.
Isa. 56:7

1. f Ayo l’ojo ‘simi fun mi,


At’agogo at’iwasu;
p Gbat’a ba mi n’nu ‘banuje
mf Awon l’o nmu inu mi dun.

2. Ayo si ni wakati na
Ti mo lo n’nu agbala Re;
Lati mo adun adura
Lati gba manna oro Re.

3. f Ayo ni idahun “Amin”


T’o gba gbogbo ile na kan,
Lekokan l’o ndun t’o nrole,
O nkoja lo sodo Baba.

4. B’aye fe f’agbara de mi
Mo ise ijo mefa re;
mf Oluwa, jo, tu ide na,
K’o so okan mi d’ominira
. Amin.
59
6.6.7.6.7.6.7.6

Ojo keje li ijo isimi Oluwa Olorun re. Eks. 20:10.

1 . mf Ose, ose rere,


Iwo ojo simi;
O ye k’a fi ojo kan,
Fun Olorun rere;
B’ojo mi ba m’ekun wa,
Iwo n’oju wa nu;
Iwo ti s’ojo ayo,
Emi fe dide re.

2 . f Ose Ose rere,


A ki yo sise loni;
A o f’ise wa gbogbo
Fun aisimi ola.
Didan l’oju re ma dan,
‘Wo arewa ojo;
Ojo mi nso ti lala,
Iwo nso ti ‘simi.

3. f Ose Ose rere,


Ago tile nwipe,
F’Eleda re l’ojo kan,
T’O fun o n’ijo mefa:
A o fi ‘se wa sile,
Lati lo sin nibe,
Awa ati ore wa,
Ao lo sile adua.

4. mf Ose, Ose rere,


Wakati re wu mi;
Ojo orun ni ‘wo se,
‘Wo apere orun;
mp Oluwa, je ki njogun
‘ Simi leyin iku;
Ki nle ma sin O titi,
Pelu eniyan Re.
Amin.
60
6.6.6.6.8.8.
Ki eyin ki o si ma pa ojo isimi mi mo, ki eyin ki o si bowo fun ibi mimo mi: Emi ni Oluwa.
Lef. 19:30.

1. f Ji, eyin mimo ji,


E k’ojo owo yi,
E fi orin iyin
At’ayo juba Re;
Wa bukun ojo t’a bukun
Eya isimi ti orun.

2. f Ni oro rere yi
L’Oluwa ji dide,
O fo ‘lekun iku,
O segun ota wa;
O si n gb’ejo wa ro loke,
O nkore eso ife Re.

3. ff Kabiyesi, Oba!
Hosana ndum loke;
Aye l’ohun ‘rele;
Si ngba iyin Re ko;
Yiye l’Od’agutan t’apa,
Lati wa, lati joba lae.
Amin.
61
7.7.7.7
Nibe ni awon igbekun simi po, nwon ko si gbohun amunisin mo. Jobu 3:18.

1. mf Imole, ojo ‘simi


Je l’o ku mo wa l’oju,
B’igbat’orun iba wo,
Fun ajo onigbagbo.

2. mf B’imole ti nrekoja,
Oru t’aso bo aye;
Gbogbo nkan dake roro,
N’ipari ojo ‘simi.

3. Alafia kun aye;


Ti Olorun mimo ni,
Apere t’inu okan
Ti o bo lowo ese.

4. Sibe Emi duro ti


Awon t’o nsin l’asale,
T’o gbe okan won s’oke,
T’o nsare si ebun na.

5. p Jesu je k’isimi wa
Je ti ayo ninu Re,
pp Tit’okan wa y’o simi,
Nibi ‘simi ailopin.
Amin.
62
L.M.
Ni ijo mefa ni iwo o sise. Eks. 20:9

1. f Ojo isimi Olorun


Ojo ti o dara julo;
Ti Olorun ti fi fun wa,
K’awa k’o simi ninu re.

2. Ijo mefa l’O fi fun wa,


K’a fi se ise wa gbogbo;
Sugbon ojo keje yato,
Ojo ‘simi Olorun ni.

3. mf K’a fi ‘se asan wa sile,


Ti awa nse n’ijo mefa;
Mimo ni ise ti oni,
Ti Olorun Oluwa wa.

4. f A para de nisisiyi
Ninu ile Olorun wa;
Je k’a korin didun si I,
Li owuro ojo oni.

5. Ni kutukutu ‘jo keje


Ni ojo isimi mimo
ff Je k’a jumo korin didun,
Je k’a si jumo gbadura.
Amin.
63
S.M.
Won nkigbe li ohun rara, wipe, Yio ti pe to Oluwa? Ifi. 6:10.

1. f A be, a fe ri O,
Ojo ‘simi rere
Gbogbo ose a ma wipe,
Iwo o ti pe to?

2. O ko wa pe Kristi
f Jinde ninu oku;
Gbogbo ose a ma wipe,
Iwo o ti pe to?

3. O so t’ajinde wa
Gege bi ti Jesu;
Gbogbo ose a ma wipe,
Iwo o ti pe to?

4. mf Iwo so t’isimi,
T’ilu alafia;
T’ibukun eniyan mimo,
Iwo o ti pe to!
Amin.
64
8.7.8.7
Oluwa si simi nijo keje. Eks. 20:11.

1. f Akoko odun at’osu,


Gbogbo won l’Olorun da;
Ojumo ni fun ise wa,
Oru si ni lati sun.

2. O si da ojo isimi;
N’nu ‘jo meje, O mu ‘kan,
K’eniyan ba le r’aye se
Ati sin Olorun won.

3. L’ojo mefa ni k’a sise,


B’o ti ye ni ki a se;
L’ojo keje je k’apejo,
Ni ile Olorun wa.

4. L’ojo na yi a ngbadura,
A nkorin didun si I
A si nyin Olorun l’ogo,
T’o ju ohun gbogbo lo.

5. Nisisiyi korin iyin,


T’Olorun Oluwa wa:
ff Korin didun, korin soke,
Ni yiyin Oluwa wa.
Amin
65
S.M.

E dide, ki e fi iyin fun Oluwa Olorun yin lae ati laelae; ibukun si ni fun oruko Re ti o li
ogo ti o ga ju gbogbo ibukun ati iyin lo. Neh. 9:5.

1. mf Dide, yin Oluwa,


Eyin ayanfe Re;
cr F’okan, emi at’ohun re
f F’ibukun f’Olorun.

2. mf B’O tile ga ju ‘yin


Ati ibukun lo,
cr Tani k’yo beru oko Re,
f Ti ki yo si gbega.

3. mf Ina ‘mole aye


Lat’odo Olorun,
f To ete wa, m;okan soji,
di M’ero wa lo s’orun.

4. cr Olorun, l’agbara,
f Orin, igbala wa:
ff Ki gbogb’ agbara wa kede
Ife Re n’nu Kristi.

5. f Dide, yin Oluwa,


Juba Olorun re;
Yin oruko Re t’ologo
Lati isiyi lo.
Amin.
66
12.10.12.10.D
E fi iyin fun Oluwa, OD. 106:1.

1. f Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa


Ki aye k’okiki ife Re nla;
Fi iyin fun! eyin Angeli ologo
F’ola at’ogo fun oruko Re
mf B’olusoaguntan, Jesu y’o to omo Re
L’apa Re l’ongbe wa le l’ojojo
Eyin eniyan mimo ti ngb’oke Sion
f Fi iyin fun pelu orin ayo

2. Fi iyin fun, Jesu olurapada wa,


mp Fun wa, o t’eje Re sile, O ku,
cr On ni apata ati reti ‘gbala wa,
f Yin Jesu ti a kan m’agbelebu,
mf Olugbala t’o f’ara da irora nla,
di Ti a fi ade egun de lori,
p Eniti a pa nitori awa eda
mf Oba ogo njoba titi laelae.

f Fi iyin fun Jesu, olurapada wa


Ki a riwo iyin gba orun kan,
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se l’oba gbogb’eyin alagbara
A segun iku; fi ayo royin na ka
mp Isegun re hada, isa oku?
cr Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
‘Tori O l’agbara lati gbala.
Amin
67
10.11.10.11. & Ref.
Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD. 89:1.

1. f Em’oyin Oluwa fun ife Re,


A we mi nin’eje olurapada
mf Eje na t’onsan nib’agbelebu
A we mi nin’eje olurapada
f Ogo, ogo, ogo f’odagutan
O gba mi lowo ese mo si di mimo
ff Ogo, ogo, ogo f’odagutan,
A we mi ni n’eje olurapada.

2. f Ore-ofe mu mi sun m’odo Re


A we mi ni n’eje olurapada
Em’ o korin soke, aye y’o gbo,
A we mi ni n’eje olurapada.

3. Alafia wo l’oto yi l’okan mi?


A we mi ni n’eje olurapada;
Ayo mimo na ko se f’enu so.
A we mi ni n’eje olurapada.

4. ff Emi o ma gb’ohun iyin s’oke


A we mi ni n’eje olurapada
Okan mi y’o ma korin lojojo
A we mi ni n’eje olurapada
. Amin
68
11.11.11.11. & Ref.
E korin titun si Oluwa; nitoriti O ti se ohun iyanu. OD. 98:1.

1. f Eyin Oba ogo, on ni Olorun,


Yin fun ‘se ‘yanu ti o ti fihan,
O wa pe l’awon ero mimo l’ona
O si je imole won l’osan l’oru
Eyin angeli didan lu duru wura,
Ki gbogbo nyin juba t’enwo oju Re
Ni gbogbo ‘joba Re, b’aye ti nyi lo
Ise Re y’o ma yin,
Ise Re y’o ma yin,
Fi ibukun fun Oluwa okan mi

2. E yin fun ‘rapada, ti gbogbo okan,


Eyin fun orisun imularada,
Fun inu rere ati itoju Re,
Fun ‘daniloju pe o ngbo adura,

3. Eyin fun idanwo, bi okun ife,


T’o nso wa po mo awon ohun orun
Fun ‘gbagbo ti nsegun ‘reti ti ki sa,
Fun ile ogo t’o ti pese fun wa.
Amin
69
L.M
Oruko Oluwa ni ki a yin OD.113:3

1. f B’oruko Jesu ti dun to,


Ogo ni fun oruko Re,
O tan banuje at’ogbe
Ogo ni fun oruko Re
Ogo f’oko Re, Ogo f’oko Re
Ogo f’oruko Oluwa
Ogo f’oko Re, Ogo f’oko Re
Ogo f’oruko Oluwa.

2. O wo okan to gb’ogbe san


Ogo ni fun oruko Re
Onje ni f’okan t’ebi npa,
Ogo ni fun oruko Re.

3. O tan aniyan elese


Ogo ni fun oruko Re
O fun alare ni simi
Ogo ni fun oruko Re

4. Nje un o royin na f’elese


Ogo ni fun oruko Re
Pe mo ti ri olugbala
Ogo ni fun oruko Re
. Amin
70
6.6.8.4.D
E yin oruko Oluwa Olorun yin,Eniti o fi iyanu ba yin lo Joe2:26

1. f Yin Olorun Abra'am,


Ti O njoba l'oke,
Eni t'O ti wa titi lae
Olorun 'fe
“Jehofa nla l'Emi”
Gbogbo eda jewo,
Mo fi 'bukun f'oruko Re
Titi laelae.

2. mf Yin Olorun Abra'am,


Nip'ase Eni ti
Mo dide, mo si wa 'tunu
Lowo 'tun Re;
Mo ko aye sile;
Ogbon at' ola re;
On nikan si ni ipin mi
At’ asa mi.

3. f On na ti se 'leri;
Mo gbekele eyi;
Un o fi iye idi goke
Lo si orun
Un o ma wo oju Re
Un o si yin ipa Re,
Un o korin 'yanu t'or'ofe
Titi laelae.

4. di B'agbara eda pin,


T'aye at'esu nde,
Un o d'ojuko ona kenan'
Nipa 'se Re
Un o re odo koja
Bi jesu wa lokan
Un o koja n'nu igbo didi
Lo s'ona mi.

5. mf Oba Oke orun


Olor' angeli nke
p Wipe “Mimo, Mimo, Mimo”
Oba titi
cr En'ti ki yi pada,
f Ti y'o si wa laelae
ff Jehofa baba, “Emi ni”,
Awa yin O.

6. f Gbogb' egbe asegun


Yin Olorun loke,
Baba, Omo at' Emi, ni
Nwon nke titi,
ff Yin Olorun Abra'am!
Un o ba won korin na,
Tire l'agbara at ola
Pelu iyin. Amin.
71
7.7.7.7
Nitori ti anu Re duro laelae OD.136:1
1. mf E je k’a f’inu didun,
Yin Oluwa olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju.

2. On nipa agbara Re
F’imole s’aye titun,
Anu Re, o wa titi
Lododo dajudaju.

3. O mbo gbogb’eda ‘laye


O npese fun anini won,
Anu Re, o wa titi
Lododo dajudaju

4. cr O ‘bukun ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu Re, o wa titi
Lododo dajudaju.

5. f E je k’a f’inu didun


Yin Oluwa olore,
Anu Re, o wa titi
Lododo dajudaju.
Amin
72
L.M.
E ho iho ayo si Oluwa, eyin ile gbogbo.OD. 100:1.

1 f Niwaju ite Jehofa,


E f’ayo sin, oril’ede
Mo p’Oluwa, on nikan ni,
O le da, O si le parun.

2. mp Ipa Re, laisi ran wo wa,


F’amo da wa ni eniyan;
p Nigba t’a sako b’aguntan
cr O tun wa mu si agbo Re.

3. f A o f’orin sunmo ‘le Re


Lohun giga l’ao korin;
Ile, ‘legbarun ahon re
Y’o f’iyin kun agbala Re.

4. Ase Re gboro k’agbaye,


Ife Re po b’ayeraye;
Oto Re y’o duro laelae
Gbat’odun o dekun ‘yipo. Amin.
73
C.M.

Emi o ma fi ibukun fun Oluwa nigbagbogbo. OD. 34:1.

1. mf N’nu gbogbo ayida aye


Ayo on wahala:
cr Iyin Olorun ni y’o ma
Wa l’enu mi titi.

2. f Gbe Oluwa ga pelu mi,


Ba mi gb’oko Re ga:
mp N’nu wahala, ‘gba mo ke pe
f O si yo mi kuro.

3. Ogun Olorun wa yika


Ibugbe Oloto;
Eniti o ba gbekele,
Yio ri igbala.

4. mf Sa dan ife Re wo lekan,


‘Gba na ‘wo o mo pe,
Awon t’o di oto Re mu
Nikan l’eni ‘bukun.

5. mf E beru Re, eyin mimo,


Eru miran ko si;
cr Sa je ki ‘sin Re j’ayo yin
f On y’o ma toju yin.

Amin.
74
C.M.

Kili emi o fi fun Oluwa, nitori gbogbo ore Re simi? OD. 116:12.

1. f Fun anu t’o po b’iyanrin,


Ti mo ngba lojumo;
Lat’odo Jesu Oluwa;
Ki l’emi o fi fun?

2. p Kini un o fi fun Oluwa,


Lat’ inu okan mi?
Ese ti ba gbogbo re je,
Ko tile jamo nkan.

3. cr Eyi l’ohun t’emi o se


F’ohun t’O se fun mi:
Em’o mu ago igbala,
Un o kepe Olorun.

4. mf Eyi l’ope ti mo le da,


Emi osi, are;
Em’o ma soro ebun Re,
Un o si ma bere si.

5. Emi ko le sin boti to,


Nko n’ise kan to pe,
f Sugbon em’o sogo yi pe,
Gbese ope mi po.
Amin.
75
C.M
Emi.mi si yo si OlorunOlugbala mi,Lk,1:47

1. f Emi ‘ba n’egberun ahon,


Fun ‘yin olugbala,
Ogo Olorun oba mi
Isegun ore Re.

2. p Jesu t’o seru wa d’ayo


T’o mu banuje tan
Orin ni l’eti elese
cr Iye at’ilera.

3. mfO segun agbara ese


O da onde sile
di Eje Re le w’eleri mo,
p Eje Re seun fun mi.

4. cr O soro oku gb’ohun Re


O gba emi titun
Onirobinuje y’ayo
Otosi si gbagbo.

5. f Odi, e korin iyin Re


Aditi, gbohun Re
Afoju, olugbala de,
Ayaro, fo f’ayo.

6. Baba mi at’Olorun mi,


Fun mi ni ‘ranwo Re;
ff Ki nle ro ka gbogbo aye,
Ola oruko Re.
Amin
76
10.10.11.11
Oluwa Olorun ,mi lowo tobi jojo OD.104:1

1. f E wole f’oba, ologo julo,


E korin ipa ati ife Re:
Alabo wa ni at’eni igbani,
O ngbe ‘nu ogo, eleru ni iyin.

2. E so t’ipa Re, e so t’ore Re,


‘ Mole l’aso Re, gobi Re orun
cr Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je
Ipa ona Re ni a ki si le mo.

3. mf Aye yi pelu ekun ‘u\yanu Re


Olorun agbara Re l’oda won,
O fi idi re mule, ki si le yi
O si f’okun se aso igunwa Re.

4. cr Enu ha le so ti itoju Re?


Ninu afefe ninu imole
di Itoju Re wa ni n’odo ti o nsan
p O si wa ninu iri ati ojo.

5 mp Awa erupe aw’alailera


‘Wo l’agbekele, o ki o da ni
cr Anu Re rorun o si le de opin
f Eleda, Alabo, Olugbala wa.

6. ff ‘Wo Alagbara onife julo,


B’awon angeli ti nyin O loke
di Be l’awa eda Re, niwon t’a le se
cr Ao ma juba Re, ao ma yin O
. Amin.
77
C.M.
Oun li Oluwa awon Oluwa ati Oba awon Oba. Ifi. 17:14.

1. f Gbogbo aye, gbe Jesu ga.


di Angel’, e wole fun:
cr E mu ade Oba Re wa,
f Se l’Oba awon oba.

2 . mf Ese l’Oba eyin Martyr,


Ti npe ni pepe Re:
cr Gbe gbongbo igi Jese ga,
f Se l’Oba awon oba.

3. mf Eyin iru omo Israel’,


Ti a ti rapada;
cr E ki Eni t’O gba yin la,
f Se l’Oba awon oba.

4. p Gbogbo eniyan elese


Ranti ‘banuje yin;
cr E te ‘kogun yin s’ese Re,
f Se l’Oba awon oba.

5. ff Ki gbogbo orile ede,


Ni gbogbo agbaye;
Ki won ki, “Kabiyesile”
Se l’Oba awon oba.

6. mf A ba le pel’awon t’orun,
Lati ma juba Re;
cr K’a bale jo jumo korin,
ff Se l’Oba awon oba.

Amin
78
8.7.8.7.8.7
Mo gbohun nla kan ti opolopo eniyan lorun, wipe Aleluyah. Ifi. 19:1.

1. f Aleluya! orin t’o dun,


Ohun ayo ti ki ku;
Aleluya! orin didun,
T’awon t’o wa lorun fe;
N’ile ti Olorun mi ngbe
Ni won nko tosantoru.

2. Aleluya! Ijo t’orun,


Ele korin ayo na
Aleluya! orin ‘Segun
Ye awon ta rapada,
Awa ero at’alejo
di Iyin wa ko nilari.

3. mp Aleluya! orin ayo


Ko ye wa nigba gbogbo
Aleluya! ohun aro.
Da mo orin ayo wa;
p Gba t’awa laye osi yi
di A ni gbawe fese wa.

4. crIyin dapo m’adura wa


Gbo tiwa, Metalokan!
Mu wa de ’waju Re layo
K’ar’ Od’agutan t’a pa
f K’a le ma ko Aleluya
Ni be lae ati laelae.
Amin.
79
8.7.8.7.4.7.
Fi ibukun fun Oluwa, iwo okan Mi. OD.103:1

1. f Okan mi yin Oba Orun


Mu ore wa sodo Re
mpWo ta wosan t’a dariji
cr Ta l’aba ha yin bi Re?
Yin Oluwa, Yin Oluwa
f Yin Oba Ainipekun

2. mf Yin fun anu t’o ti fi han


F’awon Baba ‘nu ponju,
Yin I Okan na ni titi
O lora lati binu
f Yin Oluwa! Yin Oluwa
Ologo n’nu otito.

3. p Bi Baba ni O ntoju wa
O si mo ailera wa
Jeje l’o ngbe wa lapa Re
O gbawa lowo ota
Yin Oluwa! Yin Oluwa
Anu re yi aye ka

4. ff Angel ejumo bawa bo


Eyin nri lojukoju
Orun, Osupa e wole
Ati gbogbo agbaye
E ba wa yin! E ba wa yin!
Olorun Olotito.
Amin
80
L.M.
Emi o s ti iseun ife Oluwa. Isa. 63:7

1. I Ji, okan mi, dide l’ayo


Korin iyin Olugbala,
Ola Re bere orin mi;
p ‘Seun ife Re ti po to!

2. mf O ri, mo segbe n’isubu,


Sibe O fe mi l’a fe tan;
O yo mi ninu osi mi;
p ‘Seun ife Re ti po to!

3. mf Ogun ota dide si mi,


Aye at’esu ndena mi,
On mu mi la gbogbo Re ja
‘Seun ife Re ti po to!

4. f ‘Gba ‘yonu de b’awosanma


T’o su dudu, t’o nsan ara
O duro ti mi larin re;
‘Seun ife Re ti po to!

5. ‘Gba gbogbo l’okan ese mi,


Nfe ya l’eyin Oluwa mi,
Sugbon bi mo ti ngbagbe Re
Iseun ife Re ki ye
. Amin
81
7.7.8.7.D
Ninu iponju li awa o de ijoba orun. Ise A. 14:22.

1. f Olori ijo t’orun


L’ayo l’a wole fun O
Ki o to de, ijo t’aye
Y’o ma korin bi t’orun.
ff A gbe okan wa s’oke,
Ni ‘reti t’o ni ‘nukun:
Awa kigbe, awa f’iyin
F’Olorun igbala wa.

2. ff ‘Gbat’ awa ninu ‘ponju


T’a nkoja ninu ina
cr Orin ife l’awa o ko
Ti o nmu wa sun mo O:
f Awa sa pe, a si yo
Ninu ojurere Re:
ff Ife t’o so wa di Tire
Y’o se wa ni Tire lae.

3. p Iwo mu awon eniyan Re


Koja isan idanwo
cr A ki o beru wahala,
Tori o wa nitosi
mf Aye, ese, at’Esu
Ko juja si wa lasan
f L’agbara Re a o segun
A o si ko orin Mose.

4. mf Awa f’igbagbo r’ogo


Ti o tun nfe fi wa si:
cr A kegan aye nitori
Ere nla iwaju wa
p Bi o ba si ka wa ye
Awa pelu stefen t’o sun
Y’o ri O bi ti o duro
Lati pe wa lo s’orun.
Amin
82
L.M.
E fi ayo sin Oluwa. OD. 100:2.

1. f Gbogbo eyin ti ngbe aye


E f’ayo korin s’Oluwa;
F’iberu sin, e yin l’ogo
E wa s’odo Re, k’e si yo.

2. Oluwa, On ni Olorun,
Laisi ‘ranwo wa O da wa;
Agbo Re ni wa, O mbo wa;
O si fi wa s’agutan Re.

3. Nje, f’iyin wo ile Re wa


F’ayo sunmo agbala Re;
Yin, k’e bukun oruko Re.
‘ Tori o ye be lati se.

4. Ese! Rere l’Olorun wa,


Anu Re o wa titi lae,
Oto Re ko fi ‘gbakan ye,
O duro lat’irandiran.
Amin.
83
8.8.6.
Emi o soro iyin olanla Re ti o logo, ati ise iyanu Re. OD. 145:5.

1. mf Si O Olutunu Orun
Fun ore at’agbara Re,
f A nko, Aleluya.

2. Si O, ife eni t’O wa


Ninu Majemu Olorun
A nko, Aleluya.

3. Si O, agbara Eni ti
O nwe ni mo, t’o nwo ni san
A nko, Aleluya.

4. Si O, Oluko at’ore,
Amona wa toto d’opin,
A nko, Aleluya.

5. mf Si O, Eniti Kristi ran,


f Ade on gbogbo ebun Re,
ff A nko, Aleluya.
Amin.
84
11.12.12.10
Won ko simi li osan ati li oru wipe, Mimo, Mimo, Mimo, Oluwa Olorun Olodumare.
Ifi. 4:8.

1. p Mimo, Mimo, Mimo Olodumare


mf Ni kutukutu n’iwo o gbo orin wa
p Mimo, Mimo, Mimo Oniyonu jul
f Ologo meta, lae olubukun.

2. mf Mimo, Mimno, Mimo! awon t’orun nyin


Won nfie ade wura won le l’e yi ‘te ka
cr Kerubim, Serafim nwole niwaju Re
f.di Wo t’o ti wa, t’o si wa titi lae.

3. p Mimo, Mimo, Mimo, b’okunkun pa o mo


Bi oju elese ko le ri ogo Re
mf Iwo nikan l’o mo, ko tun s’elomiran
Pipe ‘nu agbara ati n’ife.

4. fMimo, Mimo, Mimo! Olodumare


ff Gbogbog ise Re n’ile l’oke l’onyin O
cr Mimo, Mimo, Mimo! Oniyonu julo
ff Ologo meta lae olubukun.
Amin
85
6.6.4.6.6.6.4.
Tani ki yio ,Oluwa ti ki yio si fi ogo fu oruko Re Nitoripe nikansoso ni Mimo ifi 15:4

1. f Baba oke orun


T'imole at'ife
Eni 'gbani
'Mole t'a ko le wo
Ife t'a ko le so
Iwo Oba airi
Awa yin O.

2 Kristi Omo laelae


Wo l'o di eniyan
Olugbala
Eni giga julo,
Olorun imole,
Ai da at'ailopin
A ke pe O.

3. f Iwo Emi Mimo,


T'ina Pentikosti Re
Ntan titi lae.
Ma sai tu wa ninu
p L'aye aginju yi
cr 'Wo l'a fe, 'Wo la nyin
A juba Re

4. f Angel elu duru,


K'orin t'awa ti n yin
p Jumo dalu;
Ogo fun Olorun
ff Metalokan soso;
A yi n O tit'aye
Ainipekun.
Amin
86
7.7.7.5.
Awon eni-rapada Oluwa yio pada, won o si wa si Sioni ti
awon ti orin; ikanu ati ofo yio fo lo. Isa. 51:11.

1. f Olorun Metalokan
Oba ile at’okun
Gbo ti wa bi a ti nko
Orin iyin Re.

2. f ‘Wo imole l’owuro


Tan ‘mole Re yi wa ka
Je ki ebun rere Re
p M’aya wa bale.

3. f ‘Wo ‘mole ni gb’orun wo


K’a ri idariji gba
Ki alafia orun
p F’itura fun wa.

4. f Olorun Metalokan!
Isin wa l’aye ko to!
A nreti lati dapo
Mo awon t’orun
. Amin.
87
6.6.6.6.8.8
E fi iyin fun Oluwa. OD. 146:1.

1. mf A f’iyin ailopin
Fun Olorun Baba,
Fun ore aye wa
At’ireti t’orun
O ran omo Re ayanfe
p Lati ku fun ese aye.

2. f A f’iyin ailopin
Fun Olorun Omo
p T’o f’eje Re ra wa,
Kuro ninu egbe,
Nisiyi, O wa, O njoba
O nri eso irora Re.

3. f A f’iyin ailopin
Fun Olorun Emi,
Eni f’agbara Re
So elese d’aye
O pari ise igbala
O si fayo orun k’okan.

4. f A f’ola ailopin
Fun Olodumare,
‘Wo Ologo meta
Sugbon okan soso,
B’O ti ju imo wa lo ni,
ff A o ma f’igbagbo yin O.
Amin
88
7.7.7.7.
Eniti o nfi onje fun eda gbogbo; nitori anu Re duro laelae. OD. 136:25.

1. f Yin Olorun oba wa


E gbe ohun iyin ga
Anu Re, o wa titi,
Lododo dajudaju

2. mf Yin Enit’ o da orun


Ti o nran lojojumo
f Anu Re, o wa titi
L’ododo dajudaju

3. mpAti Osupa l’oru


Ti o ntan ‘mole jeje
f Anu Re, o wa titi
L’ododo dajudaju

4 mf Yin Enit’o m’ojo ro,


T’o mu irugbin dagba,
f Anu Re, o wa titi
L’ododo dajudaju

5. mf Ent’o pase fun ‘le


Lati mu eso po si
f Anu Re, o wa titi
L’ododo dajudaju

6. f Yin fun ikore oko,


O mu ki aka wa kun,
, Anu Re ,o wa titi
L’ododo dajudaju

7. mp Yin f’onje t’o ju yi lo


Eri ‘bukun ailopin
f Anu Re, o wa titi
L’ododo dajudaju.

8. un Ogo f’oba olore


Ki gbogbo eda gberin
Ogo fun Baba, omo
At’Emi metalokan.
Amin

89
6.7.6.7.6.6.6.6.
Olorun yi, Olorun wa ni lae ati laelae. OD. 48:14.

1. f A f’ope f’Olorun
L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu
N’nu eni t’araye nyo:
mf ‘Gba t’awa l’omo ‘owo
On na l’ntoju wa
O si nf’ebun ife
Se ‘toju wa sibe
2. mf Oba onib’ore
Ma fi wa sile laelae
Ayo ti ko l’opin
On ‘bukun y’o je ti wa
Pa wa mo n’nu ore
To wa, gb’a ba damu;
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun

3. un K’a f’iyin on ope


ff F’Olorun, Baba, Omo,
Ati Emi Mimo
Ti o ga julo lorun,
Olorun kan laelae
T’aye at’orun mbo,
Be l’o wa d’isiyi
Beni y’o wa laelae.
Amin
90
C.M.
Emi o si fi ota sarin iwo ati obirin na, ati sarin iru-omo re
ati iru-omo re. On o foo li ori, iwo yio si pa a ni gigise. Gen. 3:15.

1. f Iyin f’Eni mimo julo


L’oke ati ni ‘le
Oro Re gbogbo je ‘yanu,
Gbogb’ona Re daju.

2. mf Ogbon Olorun ti po to
p ‘Gbat’eniyan subu;
cr Adam’ keji wa s’oju ‘ja
f Ati lati gbala.

3. mf Ogbon ife! P’eran ara


p T’o gbe Adam’ subu
cr Tun b’ota ja ija orun
f K’o ja, k’o si segun.

4. mf Ati p’ebun t’o j’or-ofe


So ara di otun
p Olorun papa tikare
J’Olorun ninu wa.

5. mf Ife ‘yanu ti Eni ti


O pa ota eniyan
Ninu awo awa eniyan
Je irora f’eniyan.

6. p Nikoko, ninu ogba ni


Ati l’ori igi
cr T’o si ko wa lati jiya
p T’o ko wa lati ku.

7. f Iyin f’Eni mimo julo


L’oke ati nile
Oro Re gbogbo je ‘yanu
Gbogb’ona Re daju.
Amin.
91
8.7.8.7.4.7.
Jesu Kristi, eleri Olooto, Akobi ninu awon oku. Ifi. 1:5.

1. f Oluwa gunwa lori’te


mf Akobi awon t’o sun
On nikan l’Onigbeja wa
To ngbe wa leke ota
cr Aleluya, Aleluya
f Jesu li Onje Iye.

2. mf Awa njuba, awa nsape


f Kabiyesi Oba wa,
mf Busi igbagbo wa loni
K’a le tubo mo O si,
cr Aleluya, Aleluya
Iwo njoba larin wa.

3. mp Bi a ko tile ri O
Bi t’awon ti igbani,
cr A wa at’awon Angeli
Nyin iru-omo Jese
Aleluya, Aleluya
Tewo gba ijosin wa.

4. Od’agutan t’a fi rubo


Ti s’etutu f’ese wa
Ko tun si ebo miran mo
Eje Re ti to fun wa.
Aleluya, Aleluya
Eje na lo new wa mo.

5. O nfi onje iye bo wa


Manna didun lat’orun
K’orun at’aye korin na
Orin ‘yin s’Od’agutan.
Aleluya, Aleluya
O jinde, O si goke
. Amin.
92
8.6.8.6.7.7.7.4.&Ref.
Je ki gbogbo eniyan ki o yin O. OD.67:3.

1 f Gbe Oluwa ga pelub mi


Eyin eniyan re
Ki gbogbo eda alaye
Ma yo l’oruko Re
Fun ife ti O nfihan
Fun isimi l’okan wa
Fun igbala kikun Re,
Tire l’ope.
Ki gbogbo wa f’ope fun
Ki gbogbo wa f’ope fun
Ki gbogbo wa yin oruko
Oluwa wa
Titi laelae, ani, titi laelae
Ki gbogbo wa f’ope fun
Ki gbogbo wa f’ope fun
Ki gbogbo wa yin oruko
Oluwa
Titi laelae.

2 Eyin fun iwa –mimo Re,


Fun ore-ofe Re,
Korin iyin fun eje Re
To fi ra wa pada
Ife lo fi wa wa ri
Ninu ira ese wa
O f’ona iye han wa
E f’ope fun.

3 Emi ‘ba l’egberun ahon,


Nko le royin na tan;
Ife Re si mi po jojo,
Ago ‘bukun mi kun,
Ore-ofe ti ki ye,
Alafia bi odo
Lat’odo Olubukun;
E f’ope fun.
Amin.
93
11.11.11.11.& Ref.
E fi ogo fun Oluwa. OD.29:2.

1. f Ogo ni f’Oluwa to se ohun nla


Ife lo mu k’O fun wa ni Omo Re,
Enit’O f’emi Re lele f’ese wa
To si silekun iye sile fun wa.
ff Yin Oluwa, Yin Oluwa,
F’iyin fun Oluwa
Yin Oluwa, Yin Oluwa,
E yo niwaju Re
Ka to Baba wa lo l’Oruko Jesu,
Jek’a jo fogo fun Onise-‘yanu.

2. f Irapada kikun ti eje Re ra


F’enikeni t’o gba ileri Re gbo,
Enit’o buruju b’o ba le gbagbo,
Lojukanna y’o ri idariji gba.

3. f O s’ohun nla fun wa, O da wa l’ola


Ayo wa di kikun ninu Omo Re
Ogo ati ewa irapada yi
Y’oya wa lenu ‘gbat’a ba ri Jesu.
Amin
94
D.S.M.
Li ori Re ni ade pupo wa. Ifi. 19;12

1 f E de l’ade pupo
Od’agutan Baba;
Gbo bi orin orun ti bo
Orin gbogbo mole:
Ji, okan mi korin
T’Eni to ku fun O,
Se l’oba re to ga julo
Titi ati laelae.

2 f S’omo Wunsia l’oba!


Om’Olorun t’a bi
Ti ade Re nmi legbe fun
Ami isegun Re;
Silo t’a so tele,
Eka igi Jese,
Olus’agutan agbo re,
Omo ti betllehem.

3 f S’Oluwa ye l’oba
To segun iboji,
To si ji dide ni ‘segun
F’awon to wa ‘gbala
Orin ogo la nko yi
T’Eni to ku, to ji.
O ku ko ba mu iye wa
O ye ki ‘ku le ku.

4 f Se l’oba alafia!
‘Joba Re k’yo lopin;
Nibiti ogun wole fun
Ife ati iyin
Ati yika ese
Re ti a kan niso
Egberun ede ni ‘dapo
Yo korin didun si.

5 f Se Oluwa loba
Ti O gunwa loke
Se l’oba ti a fun l’oko
Iyanu ‘ti ife;
E de l’ade pupo,
Awon ti ngbe aye
Ati gbogbo oba aye.
N’tor’On l’oba eda.

6 f Se l’oba gbogbo ‘gba,


Oba ayeraye,
Eleda gbogbo irawo,
Agba ‘yanu leyi:
Olurapada wa!
To ku nitori mi;
Iyin re ki yo lopin lae
Laelae ati laelae.
Amin.
95
14.14.4.7.8.
Nitori ninu Re li a ti da ohun gbogbo, ohun ti mbe li orun ati ohun ti mbe li aye Kol. 1:16.

1 f Yin Oluwa Olodumare, Oba Eleda


Yin okan mi to r’on ni ‘lera
Ati ‘gbala re
Arakunrin, Arabinrin sunmo ‘hin
F’ayo at’orin juba Re.

2 f Yin Oluwa, Eni t’O joba


lor’ ohun gbogbo
To dabobo, to si gbe O ro
Labe iye Re
O ha ri pe?
Gbogbo ohun toto lo se
B’ O ti lana n’ipilese.

3 f Yin Oluwa to mbukun ‘se re


to si ngbeja re;
L’otito ire ati anu re nto O
Leyin
‘Gbana ronu
Ohun t’Oluwa le se
Eni to fe o, t’o yan O.

4 f Yin Oluwa! Ki gbogb’eya


ara mi juba re
Ki gbogbo ohun t’o l’emi
wa pelu iyin Re.
Jeki iro
Amin dun jakejado,
Layo lao juba re titi.
Amin.
96
8.7.8.7.4.7.
Oluwa joba: O joko larin awon Kerubu. OD. 99:1

1. mp Olorun Oluwa l’oba


cr Aye mbe niwaju Re:
Nibi t’awon angel’ nsin I,
L’O gunwa n’ite Re
Eni mimo;
Obangiji, On l’Oba.

2. f Oba ogo li Olorun,


Sion, royin Re k’aye;
Isra-eli ti igbani,
Kede itan oto Re:
Eni mimo,
Mimo li oruko Re.

3. Li atijo, ni ‘gba ewu


T’awon ojise Rre be,
O gbo ‘gbe awon eniyan RE
N’nu eru won, O dahun,
Eni mimo;
Won ri n’tosi’gba won p’E.

4. mf Awon l’afun l’ofin mimo


Lat’inu awosanma;
Ilana mimo ti won ru,
p Mu ki O binu si won;
Eni mimo;
Won kanu fun ese won.

5. cr Sugbon Baba won fiji won,


‘Gba won tun saferi Re
mf O mura tan lati gba won
f O f’ife gba won pada:
mf Awa na nw’or’-ofe Re.

6. Baba wa n’iyonu n’nu Krist’,


Y’o mu ileri Re se:
f Wa, k’a gbe ga, gbogb’alaye;
E wa soke mimo Re!
Eni mimo;
E sin loke mimo Re.
Amin
97
C.M.
Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD. 89:1.

1. mf Olorun ‘gba’okan mi wo
Gbogbo anu Re nla,
Iran na mu ki emi kun
Fun ‘yanu, ‘fe iyin.

2. f Itoju Re fi aimoye
Itunu f’okan mi,
K’okan omode mi to mo
‘Bi ti ‘re na ti nsan.

3. mf L’ona yiyo odomode


Mo sare laiwoye:
Owo anu Re l’o to mi
Titi mo fi dagba.

4. Larin ewu, ati iku,


O nto isise mi;
Ati n’nu ikekun ese
T’o li eru julo.

5. mp Nigbat’aisan je mi l’ara,
‘Wo tun fun mi l’okun
‘Wo f’or’-ofe mu mi soji
Gbat’ese bori mi.

6. mf Fun egbegberun ebun Re,


Mo nsope lojojo;
Ati f’okan t’o m’ore Re,
Ti ngba won pel’ayo.

7. Ni gbogbo igba aye mi


Un o lepa ore Re;
di Leyin iku, l’aye ti mbo,
cr Un o tun ore Re so.

8. f Un o ma korin ope si O,
Titi ayeraye;
ff Sugbon ayeraye ko to
So gbogbo iyin Re!
Amin.

98
C.M.
Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore Re si mi. OD. 116:12

1. mf Kini un o fun Olorun mi


Fun gbogbo anu Re?
Un o gba ebun Re, un o si fi
Irele bere si.

2. cr Ago or’-ofe igbala


L’emi o f’ope gba,
Un o feyinti ileri Re,
Un o si wa f’ogo Re.

3. mf Loju awon eniyan Rre


Ni un o san eje mi,
Un o fara mi on ini mi
Fi josin f’Olorun.

4. mp Baba, gbogb’ohun ti mo ni
‘Wo l’o fi jinki mi;
Mo je omo Re laye yi,
‘Wo si ra mi pada.

5. Owo Re l’o da mi, l’o si


Da mi n’de n’nu ese;
cr Anu Re t’o tu ide mi
Si ti de mi mo O.

6. f Olorun Olodumare mi,


Un o ma kokiki Re,
Emi y’o ru ebo iyin,
Un o kepe oko Re.

7. ff E f’iyin f’Olorun ife


T’o f’ese mi ji mi,
Titi ao pelu ‘jo toke
Ko orin ti orun.
Amin.
99
1.11.11.11
Fun Oba ayeraye, aidibaje,airi,
Olorun kansoso ni ola oogo wa fun
lae ati lae.1tim. 1:17

1. mf Oba aiku, airi orisun ogbon


To wa n’u u imole t’oju kole wo,
Olubukun julo Ologo julo,
Alagbara, Olusegun, ‘wo la yin.

2. Laisimi laliduro, ni idakeje,


O njoba lo O ko se alaini;
Giga ni idajo Re bi oke nla,
Ikuku Re b’isun ire at’ife.

3. f O nte gbogbo eda alaye lorun,


Nipa imisi Re won ngbe igbe won
A ndagba,a ngbile bi ewe igi,
A si nro; sugbon bakanna l’Olorun.

4. f Baba nla Ologo Imole pipe


Awon angeli Re wole lese Re!
Iyin wa la mu wa, jo ran wa lowo,
K’a le r’ogo imole to yi O ka.
Amin.
100
7.4.7.4.5.7.4.
Ki iru awon ti o fe igbala re ki o ma wi nigbabogbo pe: “Ki a gbe Olorun ga. OD. 70:4.

1. f Oba ogo, alafia,


Un o feran Re;
Ife na ki y’o dekun,
Un o sunmo O;
N’tori O ti gbebe mi,
O ti gb’ohun mi;
O ka iwe aya mi,
O da mi n’de.

2. Fun idasile yi ni
Un o korin Re;
Gbogb’ayo okan mi ni
Un o mu fun O;
mp ‘Gba t’ese mi nke kikan,
O da mi lare:
mf ‘Gba mo pe O nikoko,
O gbebe mi.

3. f Gbogb’ojo aye mi ni
Un o fi yin O;
Mo le gbe O ga ninu
Okan mi yi:
Aye wa n’nu okan mi
T’Iwo y’o ma gbe!
Ayeraye kuru ju
Lati yin O. Amin.
101
8.8.8.8.6.6.6.6.8.
Eyin Oluwa. OD. 135:1.

1. f E yo loni pel’ohun kan,


E korin igbega soke:
Eyo, e yin Oluwa wa,
T’apa Re mu igbala wa:
Ise ife npokiki
Titobi oruko Re:
Olorunkan laelae
To to f’anu Re han;
K’eniyan mimo Re juba Re.

2. mp ‘Gba ‘banuje de, a jepe


O si gbogb’ aroye wa
Gbekele boti wu kori,
Agbeniro ni ife Re;
Mf Orin lyin ‘segun
Lokan wa y’o ko so;
Gbogb’ohun y’o lo pe;
“eyin Olorun wa:;
K’eniyan mimo Re juba Re
. Amin
102
Emi o ma yin oruko Re nitori iseun –ife Re ati otito Re. OD. 138:2.
1. f Yin Olurapada re
F’ogo f’oruko Re titi lae!
Oloto lo oun sa je
f F’ogo f’oruko Re titi lae!
Gb’oruko Re ga! F’ogo f’oko Re
Korin Alleluya titi lae
Gb’oruko Re ga f’ogo f’oko Re
Korin ‘yin s’Oluwa titi lae!.

2. mf Fun ‘bukun to nfi fun wa!


F’ogo f’oruko Re titi lae!
B’or-ofe Re ti po to
F’ogo f’oruko Re titi lae!.

3. cr Ko ha se o l’ore bi?
mf F’ogo f’oruko Re titi lae!
Kil’o ku k’o se fun o?
F’ogo f’oruko Re titi lae!.

4. cr Ife wo lo po bayi?
mfF’ogo f’oruko Re titi lae!
cr Alafia bayi wa bi?
mf F’ogo f’oruko Re titi lae!

5. ff Ki ahon mi tu lati
F’ogo f’oruko Re titi lae!
K’emi lat’ayeraye
F’ogo f’oruko Re titi lae!
Amin
103
8.8.8.5.
Gbe Oluwa ga pelu mi, ki a si jumo gbe oruko Re leke. OD. 34:3.

1. f Yin Oluwa, eyin mimo


Awa ti je ni gb’ese to?
Je k’a mu gbogbo ini wa
Wa pelu ayo.

2. mf Jesu l’Oko t’o dara ju


O nfun wa l’okun l’oju ‘ja
Ibi kan ko le de ba wa
‘Gba’a gbekele.

3. Gbeke yin le, eyin mimo


Olododo l’Olorun wa,
Ko s’ohun to le, ya awon
T’o fe l’odo Re.

4. mf F’ore ofe Re pa wa mo
K’a le tubo faramo O
Titi ao fi de ‘nu ogo
At’ayo l’orun.

5. ‘Gbana l’ao de ibi mimo


‘Gbana l’a o si di mimo
Ayo nla ti a ko so
Ni y’o je tiwa.
Amin.
104
C.M. & Ref.
Eniti o fe wa, ti o si we wa ninu eje Re kuro ninu ese wa: Tire li ogo ati ijoba lae ati lae:
Amin. Ifi. 1:5-6.

1. mf Gbo orin awon ayanfe


Orin iyin titun;
T’Od’agutan t’a se logo
Eyi ni orin won:
f “Ogo f’Eni to fe wa,
To f’eje Re we wa,
To w’ese at’ebi wa nu
Nibi ‘san iye ni”.

2. mf A fo aso wa n’n’eje Re
O si fun laulau;
Imole t’O tan s’okan wa
F’ipa oto Re han.

3. f A segun nipa eje Re


‘Gbat’esu gbogun de,
Agbara otito Kristi
Lo f’okun s’apa wa.

4. Ka juba O’d’agutan na
Baba ‘ye on mole
Tire l’ogo, ola, ipa,
‘Joba at’agbara.
Amin.
105
8.7.8.7.D.
Ohun opolopo eniyan nwipe, Alleluya. Ifi. 19:6.

1. mf Gbo orin ‘yin dida aye,


T’egberun orile nko
Orin didun bi t’angeli,
O ndun bi omi pupo –
f “Bukun, ogo, ipa, ‘gbala
Fun Olorun lor’ite,
Baba, Omo, Emi Mimo
Olola ‘lainipekun.

2. mf Titi lo, lat’oro d’ale


Lor’olukuluku ‘le
Lat’opolopo eniyan
Ilu alawo pupa,
‘Lawo dudu t’a da n’ide,
Funfun ti o po niye,
Omnira alarinkiri
De ‘le awon Arabu.

3. mf Lati ebute otutu


De ile ti o mooru,
Awon olokan gbigbona
Leba okun Pasifik’,
Lat’opo aimoye okan
Onigbagbo alayo, ogo, ipa, ‘gbala
Fun Olorun lor’ite,
Baba, Omo, Emi Mimo
Olola ‘lainipekun.

2. mf Titi lo, lat’oro d’ale


Lor’olukuluku ‘le
Lat’opolopo eniyan
Ilu alawo pupa,
‘Lawo dudu t’a da n’ide,
Funfun ti o po niye,
Omnira alarinkiri
De ‘le awon Arabu.

3. mf Lati ebute otutu


De ile ti o mooru,
Awon olokan gbigbona
Leba okun Pasifik’,
Lat’opo aimoye okan
Onigbagbo alayo,
Awon to nsona bibo Re,
Won fere de Sion’ na.

4. cr Akojo orile-ede,
Lat’inu eya ahon,
Gbo, won nkorin iyin titi,
Gbo orin ologo ni,
O b’afonifoji mole,
O si ndun lori loke,
f O ndun siwaju tit’o fi
Kun ibugbe Olorun.

5. p Gbo, didun orin na dapo


Mo orin awon t’orun,
Awon t’o koja n’nu ‘danwo
Sinu isimi loke,
cr Won wo aso alailabawon,
mf Imo ‘segun lowo won,
Won nfi duru ko Hosana,
Ni ‘waju Olorun won.

6. f “Ogo fun Eni t’o fe wa,


T’O we wa n’nu eje Re;
K’oba, alufa, ma korin
Si Baba, Olorun wa.
Keeyan mimo on Angeli,
Ko Aleluya titi:
Asegun orun apadi:
Olodumare joba”.
Amin.
106
P.M.
Ewe ati agba, nwon duro niwaju ite. Ifi. 20:12.

1. mf Awa f’ori bale fun / O Jesu,


‘Wo ti s’Olori Ijo awon / eniyan Re,
Ijo ti mbe laye yi ati lo / run pelu;
Ale/luya.

2. p ‘Wo t’oku, t’o si jin/de fun wa,


T’o mbe lodo Baba bi Ala/gbawi wa
K’ogo at’olanla/je Tire
Ale/luya.

3. mf Ati li ojo nla Pen/tikosti


Ti o ran Parakliti/si aye
Olutunu nla Re ti / mba wa gbe;
Ale/luya.

4. f Lat’ori ite Re l’o/ke orun,


L’o si now gbogbo awon o/jise Re
T’o si nsike gbogbo awon Aje/riku Re
Ale/luya.

5. f A fi iyin at’olanla f’o/ruko Re,


p N’tori iku gbogbo awon o/jise Re
Ni gbogbo ile Yo/ruba yi:
Ale/luya.
Amin
107
8.7.8.7.4.7.
Nje fun Oba ayeraye, aidibaje, airi, Olorun kansoso, ni ola ati ogo wa fun lae ati laelae.
Amin I Tim. 1:17

1. f Ogo fun Olorun Baba,


Ogo f’Olorun Omo,
Ogo fun Olorun Emi,
Jehofa, Metalokan;
f Ogo, Ogo
B’ayeraye ti nkoja.

2. f Ogo fun Eni t’o fe wa,


T’o we abawon wa nu;
Ogo fun Eni t’o ra wa,
T’o mu wa ba On j’Oba;
ff Ogo, Ogo
Fun Od’agutan t’a pa.

3. f “Ogo, ‘bukun, iyin laelae!


L’awon ogun orun nko;
“Ola, oro, ipa, ‘joba!”
L’awon eda fi nyin I,
ff Ogo, Ogo
Fun Oba awon oba
. Amin.
108
7.7.7.7.
Awa si nyin oruko re laelae. OD. 44:8.

1. mf F’oruk’Olorun loke,
T’O l’agbara at’ola,
Olorun ibi gbogbo,
N’iyin ati ogo wa.

2. F’oruko Krist’Oluwa,
Om’Olorun ti a bi,
Krist’ t’O da ohun gbogbo,
Ni k’a san ‘yin ailopin.

3. F’Olorun Emi Mimo,


Ni k’iyin pipe wa lae,
Pelu Baba at’Omo,
Okan l’oruko, l’ogo.

4. Orin t’a ti ko koja,


T’ao si ma ko lae leyi;
Ki awon iran ti mbo
Dapo korin didun na.
Amin
109
7.7.7.7.
Ogo ni fun Olorun loke Orun. Lk. 2:14.

1. f E fi ogo fun Baba,


Nipa Eni ti a wa;
O ngbo adura ewe,
O nf’eti si orin won.

2. f E fi ogo fun Omo,


Kristi, ‘Wo ni Oba wa;
ff E wa, e korin s’oke,
S’Od’agutan elese.

3. f Ogo fun Emi Mimo,


Bi ojo Pentikosti;
Ru aya awon ewe,
F’orin mimo s’ete won.

4. ff Ogo ni l’oke orun,


Fun Eni Metalokan;
Nitori ihin rere,
Ati ife, Olorun.
Amin.
110
7.7.7.5.
Awon eni irapada Oluwa yio pada, won a si wa si
Sioni ti awon ti orin, ikanu ati ofo yio si fo lo. Isa. 51:11.

1. f Olorun Metalokan,
Oba ile at’okun
Gbo ti wa bi a nko
Orin iyin Re.

2. f ‘Wo imole l’owuro,


Tan ‘mole Re yi wa ka
Jeki ebun rere Re,
M’aya wa bale.

3. f ‘Wo ‘mole nigb’orun wo


K’a ri idariji gba
Ki alafia orun
F’itura fun wa.

4. f Olorun Metalokan!
Isin wa l’aye ko to!
A nreti lati dapo
Mo awon t’orun.
Amin.
111
L.M.
Nibe ni Oluwa gbe pase ibukun, ani iye lailai. OD. 133:3.

1. f Baba orun ‘jinle ‘fe Re,


L’o wa Oludande fun wa;
p A wole niwaju ‘te Re,
mf Na ‘wo ‘dariji Re si wa.

2. f ‘Omo Baba t’O d’eniyan


Woli, Alufa, Oluwa,
p A wole niwaju ‘te Re,
mf Na ‘wo igbala Re si wa.

3. f Emi at’ayeraye lae,


Emi ti nji oku dide,
p A wole niwaju ‘te Re,
mf Na ‘wo isoji Re si wa.

4. f Jehofa, Baba, Omo, Emi,


‘Yanu, ‘jinle, Metalokan;
p A wole niwaju ‘te Re,
mf Na ‘wo Emi ‘ye Re si wa
. Amin.
112
6.6.6.6.8.8.
Oluwa, iwo li o ye lati gba ogo, ola ati agbara. Ifi. 4:11.

1. mf Baba Eleda wa,


Af’ife gbadura;
Eni t’O fun wa ni
Ona, oto, iye;
cr Fi anu ro ‘jo ‘bukun Re
S’ori awa ti njosin yi.

2. mf Baba Eleda wa,


cr A s’okan wa paya;
Okan omnira wa.
f Nyin O lopolopo;
Mi imisi Re s’okan wa,
K’orin ‘yin wa le bu jade.

3. mf Baba eleda wa,


cr ‘Wo ri iberu wa
T’o pamo l’okan wa,
p T’o nf’omije soro;
cr Ko wa lati gbekele O
Si mu wa la ewu yi ja.

4. mf Baba Eleda wa,


Je k’a f’ahon wa yin,
‘Gbat’ayo t’o jinle
Kun gbogbo okan wa;
N’nu gbogbo ayida aye,
Je k’a r’ona alafia.
Amin.
113
C.M.
A o si ma pe oruko Re ni Iyanu.Isa. 9:6

1. f Olorun Olodumare,
Baba, Omo, Emi,
Riri Eni t’a ko le mo,
Eni t’a ko le ri.

2. f Ye! Baba Olodumare,


K’a wariri fun O,
Ni gbogbo orile-ede,
Li a o ma sin O.

3. f Olorun Omo, Ore wa,


p ‘Wo t’o ra wa pada
Ma jowo wa, Olugbala!
Gba wa patapata.

4. A! Olorun Emi Mimo,


‘Wo olore-ofe;
A be O, fun wa ni imo,
K’a m’Olorun n’ife.

5. f Okansoso sugbon meta,


Eni Metalokan,
Olorun awamaridi,
Eni Metalokan!
Amin.
114
C.M.
Ibukun, ati ola, ati Ogo, ati agbara, fun eniti o joko
lori ite ati fun Odo-Agutan na lae ati laelae. Ifi. 5:13.

1 .mfA ko ‘rin s’Omo Olorun,


p Odagutan t’a pa;
Ti orun ati aye mbo,
T’O ye lati joba.

2. Si O l’awon Angeli nke,


L’ekun gbogbo orun:
p “Mimo, mimo, mim’Olorun,
T’ogo, at’om’ogun.

3. f Ijo Re li aye dapo,


di Lati ma kepe O;
Didan Olanla Olorun,
T’O l’agbara gbogbo.

4. Larin won ni gbogbo wa nfe


Lati yin eje Re;
Joba l’aye ati l’orun,
‘Wo Omo Olorun,
Amin.
115
6.6.6.6.8.8.
Oluwa, Iwo li o ye lati gba ogo, ati ola, ati agbara. Ifi. 4:11.

1. f Baba, Eleda wa,


Gbo orin iyin wa
L’aye ati l’orun,
Baba Olubukun:
cr Iwo l’ogo ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.

2. f ‘Wo Olorun Omo,


T’O ku lati gba wa;
Eni t’O ji dide,
Ti O si goke lo:
cr Iwo l’ogo ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.

3. f Si O Emi Mimo,
Ni a korin iyin:
Iwo t’o f’imole
Iye si okan wa;
cr Iwo l’ogo ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.

4. p Mimo, mimo, mimo,


N’iyin Metalokan:
L’aye ati l’orun,
f L’a o ma korin pe,
cr Iwo l’ogo ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.
Amin.
116
9.10.10.7 & Ref.
Emi o tun pada wa, Emi o si mu yin lo sodo emi tikarami. Jn. 14:3.

1. mf Jesu mbo! ko oro ayo na,


Mbo f’awon t’O f’Eje Re rapada,
Mbo lati joba b;Oluwa ogo.
Jesu y’o tun pada wa.
f Jesu y’o tun wa, y’o tun pada wa,
Jesu y’o tun pada wa,
Ho iho ayo na ka ‘bi gbogbo,
Jesu y’o tun pada wa.

2. mf Jesu mbo; Oku yio jinde,


Awon ore y’o pade pel’ayo,
Won o goke s’odo Re ni sanma,
Jesu y’o tun pada wa.

3. Jesu mbo lati da ‘yanfe nde,


Lati f’alafia f’aye ija,
Ese aro, ‘banuje y’o d’opin,
Jesu y’o tun pada wa.

4. Jesu mbo, ileri na j’oto,


Tal’awon die t’a yan ti nsoto,
Ti nduro, ti nsona fun ibewo,
Jesu y’o tun pada wa.
Amin.
117
Kiyesii, O mbo nini awosanmo. Rev. 1:7

1. mf Jesu mbo l’ofurufu pe l’ayo,


f Ojo ayo! ojo ayo!,
mf Awon t’o fe yo fo lo pade re,
f Ojo ayo! ayo nla,
Won yo pade Oluwa ni sanmo,
Gbogbo wa pelu Jesu yo wa nibe,
A o bo lowo aniyan at’aro,
Ojo ayo!, ayo nla!.

2. mf Awon obi, omo yo tun pade:


f Ojo ayo! ojo ayo!,
Arakunrin pelu arabinrin,
Ojo ayo!, ayo nla,
Won mbe l’odo Krist’ a ko ri won mo,
cr Ibanuje ni lilo won je fun wa;
Sugbon a o pade laipe pe l’ayo.
mf Ojo ayo!, ayo nla!.

3. Gbogbo wa ha setan fun bibo Re?


Ojo ayo!, ojo ayo!
Omode ati agba ha se tan!
F’ojo nla!, ojo ayo!,
A nfe lati wa l’odo Re laelae,
K’a le ma wo oju ati ewa Re,
Eyin ara, e korin nitori,
Ojo nla na t’ ao pade.

4. f Awon miran ko ni le ba wa ko
Orin ayo ti ojo na,
Sugbon gbogbo wa ni ayo mbe fun
ff Ojo ayo!, ojo nla:
mf ‘Tori Jesu nduro sibesibe,
K’a le mura tan nipa agbara Re,
Ninu ogo didan Re k’a le ni
Ibugbe l’oke orun.
Amin.
118
15.15.15.15.& Ref.
Nitorina e ma sona; nitori eyin ko mo wakati ti Oluwa nyin yio de. Mat. 24:42.

1. mf Awa nsona, awa nduro titi ‘boji y’o fi ya,


T’Oluwa pelu awon ayanfe y’o de n’nu ogo,
Nigbati a o gbo ipe Olorun jakejado,
Oku n’nu Kristi y’o si ji lati wa l’odo Re lae.
cr Awa nsona, awa nduro,
Fun imole ti ojo nla na,
Fun bibo Olugbala wa
Pelu awon ayanfe.

2. mf Awa now ona fun bibo Oba wa nla Ologo,


Eni ti yo le ibi ati okunkun lo jina,
‘Gbat’ododo ati anu Re yio bori l’aye
Ti asia Re yo si ma fe lori gbogbo aye.

3. Awa nfi ‘gbagbo wo ‘joba Re ti egberun odun,


Ati opo awon emewa Rre ti a ra pada,
Okan wa si nkepe. “Ma bo k’a ba le ri ogo Re”
Ki a le ma ba gbe ninu ogo ti ayeraye
. Amin.
119
C.M.
Nitori ti o ti be awon eniyan Re wo; O si da won ni ide Lk. 1:68.

1. f Gbo ‘gbe ayo! Oluwa de,


Jesu t’a se ‘leri;
Ki gbogbo okan mura de,
K’ohun mura korin.

2. O de lati t’onde sile


L’oko eru esu,
ff ‘Lekun ide fo n’waju Re
Sekeseke ‘rin da.

3. mf O de larin ‘baje aye


Lati tan ‘mole Re,
Lati mu k’awon afoju
Le f’oju won riran.

4. p O de, ‘Tunu f’okan ‘rora,


Iwosan f’agbogbe!
cr Pelu ‘sura or’ofe Re
Fun awon talaka.

5. f Hosana, Oba alafia,


Ao kede bibo Re;
Gbogbo orun y’o ma korin
Oruko t’a feran.
Amin.
120
8.7.8.8.7.7.7.7.7

Emi o si tun pada. Jn. 14:3.

1. f Iwo mbowa, Oluwa mi;


Iwo mbowa, Oba mi;
cr Ninu ‘tansan ewa Re,
Ni titayo ogo Re.
Mura dee, e mura dee,
Oko ‘yawo fere de,
L’oru ni igbe y’o ta,
Mura lo ko O, okan mi.

2. mf pIwo mbowa,Iwo rubo wa,


A o pade Rel’ona
cr A o ri O,a o mo O,
A o yin O, gbagbo okan
L’a o sipaya fun O,
f Orin ki l’eyi o si o je
A o tu ‘fe wa rekoja’
A o tu ‘fe wa jade
Si ese Re, Ologo.

3. mf Iwo mbowa nitoto,


A o pade Re lona
A o ri O, a o mo O
N’idapo mimo julo.
Eri ibukun ti mbo
cr Ko f’iku Re nikan Iran,
At’ife titobi Re
Sugbon bibo Re pelu
T’a nfe,t’a si nduro de.

4 f Y’o dun lati ri O njoba ,


Oluwa mi,Olufe’
cr Ki gbogbo ahon jewo Re
Iyin,Ola,ati ogo,
Ki won jumo fi fun O,
ff K’o segun k’o si gunwa
Titi de opin aye
Ninu ogo at’ola.
Amin
121
D.S.M.& Ref.
Nitoto Emi mbo kankan. Amin. Ifi. 22:20.

1. mpIjo ti nduro pe
Lati ri Oluwa,
O si wa bakan na sibe,
Ko s’alabaro fun!
Odun nyi lu odun,
Ojo ngori ojo,
Sibe lairi Oluwa re,
O wa ninu ofo
Ma bo, Jesu, ma bo.

2. mpAwon mimo l’aye


Opo won l’oti ku;
p Bi won si ti nlo l’okankan
L’a te won gbe’ra won;
pp A te won lati sun,
Ki se l’aininreti;
cr A te won lati r’eju ni,
K’ile ogo to mo,
Ma bo, Jesu ma bo!

3. Awon ota npo si,


Agbara esu nga;
Ogun ngbona, igbagbo nku,
Ife si di tutu
cr Y’o ti pe to! Baba,
Oloto, Olore!
‘Wo ki y’o koya omije
At’eje Ijo Re,
Ma bo, Jesu ma bo!

4. mf A nfe gbo ohun Re,


A nfe f’oju kan O,
K’a le gba ade at’ogo
B’a ti ngba ore Re;
f Jo, wa m’ese kuro!
At’egun at’eri,
K’o si so aaye osi yi
D’aye rere Tire
cr Ma bo, Jesu ma bo.
Amin.
122
Ohun eniti o mi aye nigbana Heb. 12:26.

1. f Oluwa, agbara fo ‘hun,


Bi ara l’oke sinai,
Awon Israeli gb’ohun re,
Won si gbon fun iberu:
Okunkun su biribiri
Ati l’otun ati l’osi,
ff Awon apata nfaya.

2. p Oluwa ife je irora,


Lori oke kalfari,
O gbe iju soke orun,
L’akoko wahala Re:
Fun wa l’oru eru egbe
Fun wa l’o teje re sile,
T’o si tu Baba l’oju.

3. mf Oba ife at’agbara


Oluwa eda gbogbo,
cr O npada bo ninu ogo
Lati wa gba ijoba
ff Ipe y’odun, angel’ y’o ho
Alleluya y’o j’orin won
L’ori esu at’iku.
Amin.
123
6.4.6.4.6.7.6.4.
O ti to Wakati nisiyi fun yin Lati ji l’oju.Rom. 13:11.

1. f Gbo ohun alore,


Ji ara ji
Jesu ma fere de,
Ji, ara, ji,
mf Omo oru ni’ sun,
Omo imole l’eyin,
Ti yin l’ogo didan,
Ji, ara, Ji.

2. mf So f’egbe t’ o ti Jji,
Ara sora,
Ase Jesu daju,
Ara, sora.
p E se b’Olusona
Ni ‘ lekun Oluwa yin,
Bi O tile pe de,
Ara, sora.

3. mf Gbo ohun iriju,


Ara sise:
Ise na kari wa,
Ara, Sise:
Ogba Oluwa,
Kun fun ‘ Se nigbagbogbo
Y’o o si fun wa l’ere,
Ara, Sise.

4. mpGb’ohun Oluwa wa,


Egbadura,
B’efek’inu Re dun,
E gbadura,
p Ese mu ’beru wa,
Alailera si ni wa,
Ni ijakadi yin.,
E gbadura.

5. f Ko orin ikeyin
Yin ara yin,
cr Mimo ni Oluwa,
Yin, ara yin
ff Ki l’o tun ye ahon
T’o fere b’ Angel’ korin
T’ y’o ro lorun titi
Yin, ara, yin
. Amin.
124
7.6.7.6.D.
Wo! Oko iyawo mbo, e jade lo pada Re. Mat. 25:6.

1. f Yo eyin onigbagbo,
Je k’imole yin tan;
Igba ale mbo tete,
Oru si fere de,
Oko iyawo dide
O fere sun mo le,
Dide, gbadura; sora
L’oru n’igbe y’o ta.

2. mpEbe fitila yin wo,


F’ororo sinu won;
E duro de ‘gbala yin
Ipari ‘se aye:
mf Awon oluso nwipe,
“Oko ‘yawo de tan
E pade Re, b’O ti mbo
Pelu orin iyin”.

3. cr Eyin wundia mimo,


Gbe ohu yin ‘soke
f Titi n’nu orin ayo
Pelu awon Angel’,
Onje iyawo setan,
Lekun na si sile,
ff Dide, arole ogo,
Oko iyawo mbo.

4. mf Jesu ‘Wo ireti wa;


F’ara Re han fun wa;
‘Wo orun t’a ti nreti,
Ran s’ori ile wa,
A gbe owo wa s’oke
Oluwa je k’a ri
Ojo ‘rapada aye
T’o mu wa d’odo Re.
Amin.
125
8.7.8.7.
Ife gbogbo orile-ede yio si de.Hag. 2:7.

1. f Wa, Iwo Jesu t’a nreti,


T’a bi lati da ni n’de,
Gba wa low’eru at’ese,
Je k’a ri isimi Re.

2. Iwon’itunu Israel’,
Ireti onigbagbo,
Ife gbogb’orile ede
Ayo okan ti nwona.

3. ‘Wo t’a bi lati gba wa la


Omo ti a bi l’Oba,
Ti a bi lati joba lae,
Je ki ijoba Re de.

4. Fi Emi Mimo Re nikan


Se akoso aya wa;
Nipa ekun itoye Re,
Gbe wa sori ite Re.
Amin.
126
7.7.8.4.
Eniti o ba to mi lehin ki yo rin ninu okunkun. Jn. 8:12.

1. mf ‘Mole t’o da gbogbo nkan,


Ni pipe, lati n’okun,
cr K’a pin, n’n’ewa on ‘bukun Re,
Wa sodo wa.

2. f ‘Mole t’o joba aye,


‘Mole t’o fun wa n’iye,
A! Imole t’o ns’atunda,
Wa sodo wa.

3. p Imole t’O wa s’aye


‘Mole t’o nw’oju eda
pp T’o ku l’okunkun b’eniyan;
Wa sodo wa.

4. mf ‘Mole t’o de ‘pa ‘rele


T’o tun lo s’oke giga,
T’o si wa pelu wa sibe
Wa sodo wa.

5. mf ‘Mole t’o nfun wa l’oye


‘Mole t’onse wa l’ewa,
Imole ti nf’ayo simi,
Wa sodo wa.

6. mpMase je k’a pe, a ri,


‘Gbat’a diju wa si O,
pp Eni ti O nfi suru kan ‘kun
Wole, ma bo.

7. mf Tire ni gbogbo ‘re wa


Tiwa ni gbogbo ibi;
Jo, le won kuro lodo Re
Wa sodo wa.

8. Mu ‘se okunkun kuro;


Di wa ni ‘hamora Re,
cr K’a rin n’nu ‘mole k’a ma so
Atunwa Re.
9. p Awa se O pupo ju,
cr Sibe, Tire l’awa se,
Je k’aye wa j’orin si O,
Wa sodo wa.

10. Wa ninu ola-nla Re


di Ni titobi ‘rele Re,
ff Wa, gbogbo aye nke pe O,
Wa sodo wa.
Amin.
127
Olurapada yio si wa si Sioni. Isa. 59:20.

1. mf Sum’odo wa Imanuel’,
Wa ra Israeli pada,
p T’o nsofo li oko eru,
Titi Jesu y’o tun pada.
ff E yo, e yo! Imanuel’,
Y’o wa s’odo wa, Israel.

2. mf Wa, opa Alade Jese,


K’o gba wa l’owo ota wa,
Gba wa l’ow’orun apadi,
Fun wa ni ‘segun l’ori ‘ku.

3. Sunmo wa, ‘Wo ila orun,


Ki bibo Re se ‘tunu wa,
Tu gbogbo isudede ka
M’ese ati egbe kuro.

4. mf Wa, Omo, ‘lekun Dafidi,


‘Lekun Orun y’o si fun O
Tun ona orun se fun wa;
Jo se ona osi fun wa.

5. Wa Oluwa alagbara,
T’o f’ofin fun eniyan Re.
Nigbani, l’or’oke Sinai,
Ninu Olanla pel’eru.
Amin.
128
L.M.
Emi o si tun pada wa. Jn. 14:3.

1. mf L’eba odo Jordani ni


Oni ‘ribomi nke wipe
f Oluwa mbo! Oluwa mbo,
E gbo ‘hin ayo! Oba mbo.

2. K’ese tan ni gbogbo okan,


K’Olorun ba le ba wa gbe;
K’a pa ile okan wa mo
Ki alejo nla yi to de.

3. Jesu, Iwo n’igbala wa,


Esan, ati albo wa,
B’itanna l’awa ba segbe
Bikose t’ore-ofe Re.

4. S’awotan awon aisan,


Gb’elese to subu dide,
Tan ‘mole Re ka bi gbogbo
Mu ewa aye bo s’ipo.

5. K’a f’iyin f’Omo Olorun;


Bibo eni mu dande wa
Eni t’a nsin pelu Baba
At’Olorun Emi Mimo.
Amin.
129
D.S.M.
E ma sora, ki e si ma gbadura. Mk. 13:33.

1. mf Iwo Onidajo,
A fere duro na
Pelu ayo tabi eru
Ni ‘waju ite Re;
Jo, pese okan wa
Fun ojo nlanla ni,
p Fi emi isora kun wa
At’emi adura.

2. f K’a ma wo ona Re
L’akoko aimo ni;
Ni gbat’Iwo sokale
Ninu Olanla Re
Iwo Emi aiku,
Lati da wa l’ejo
T’Iwo ti ogun Baba Re
At’ ore-ofe Re.

3. mf K’a le ba wa bayi,
Ni gboran soro Re
K’a ma te ‘ti s’ohun ipe,
K’a ma wo ona Re,
K’a wa ipo ayo
T’awon olubukun,
K’a si sora nigba die,
Fun simi ailopin
. Amin.
130
6.6.6.6.8.6.
E ma yo ninu Oluwa nigbagbogbo. Fili. 4:4.

1. f Oluwa ni Oba,
E bo Oluwa yin,
Eni kiku, sope,
Y’ayo ‘segun titi,
ff Gb’okan at’ohun yin soke
“E yo” mo si tun wi, “E yo”

2. Olugbala joba,
Olorun otito,
‘Gbat’O we ‘se wa nu
O g’oke lo joko.

3. O mbe l’odo Baba,


Titi gbogbo ota
Yio teri won ba
Nipa ase Tire.

4. Yo n’ireti ogo
p Onidajo mbo wa,
Lati mu ‘ranse Re
Lo ‘le ayeraye.
A fe gbo ‘hun angel nla na
ff Ipe y’o dun wipe, “E yo”.
Amin.
131
8.7.8.7.4.7.
Kiyesi i, O mbo li awosanma. Iifi. 1:7.

1. mf Wo Oluwa l’awosanma,
O mbo l’ogo l’ola Re,
Enit’a pa fun elese,
Mbo pelu angeli Re;
ff Aleluya!
O wa s’aye wa joba.

2. Gbogbo eda, wa wo Jesu,


Aso ogo l’a wo fun;
p Awon t’o gan, awon t’o pa
T’o kan mo agbelebu,
pp Won o sokun,
Bi won ba ri Messiah.

3. Awon apa iya t’O je


Han li ara didan Re,
Awon eni irapada,
Wole, fun t’ayo t’ayo;
Pel’ayo nla
L’a now awon apa na.

4. Irapada t’a ti nreti,


O de pelu ogo nla;
Awon ti a gan pelu Re
Y’o pade Re loj’orun!
ff Aleluya!
Ojo Olugbala de.

5. Beni, Amin! K’a juba Re,


Lor’ite Re ailopin,
Olugbala gba agbara;
Ogo at’ijoba Re,
Jah, Jehofa,
Olorun aiku, ma bo!
Amin.
132
8.7.8.7.8.8.7.
A o si ji awon oku dide li aidibaje. I Kor. 15:52.

1. f Olorun! Kini mo ri yi!


Opin de f’ohun gbogbo!
Onidajo araye yo,
O gunwa n’ite ‘dajo,
ff Ipe dun, iboji si tu,
Gbogbo awon oku sile,
p Mura lo ko emi mi.

2. mf Oku ‘nu Krist’ y’o ko jinde


Nigba ‘pe ‘keyin ba dun,
Won o lo ko l’awosanma,
Won o fi ayo yi ka;
Ko s’eru ti y’o b’okan won;
Oju Re da imole bo
Awon ti o mura de.

3. p Sugbon elese t’on t’eru!


Ni gbigbona ‘binu Re,
Won o dide, won o si ri
Pe, o se, won ko ba mo;
pp Ojo ore ofe koja;
Won ngbon niwaju ‘te ‘dajo,
Awon ti ko mura de.

4. cr Olorun, kini mo ri yi!


Opin de f’ohun gbogbo,
Onidajo araye yo,
O gunwa n’ite ‘ajo,
p L’ese agbelebu mo now,
‘Gbat’ohun gbogbo y’o koja,
cr Bayi ni mo nmura de
. Amin.
133
8.8.8.8.7.7.6.6.8.
Oluwa awon omo ogun, On na li Oba ogo. OD. 24:10.

1. f Egbe ori yin soke,


Eyin l’ekun ayeraye,
Wo! Oba nla, Ologo mbo,
Lati gunwa lori ‘te Re,
Tani Oba ogo yi?
mpTani Oba ogo yi?
cr Oluwa t’O ni ‘pa,
Asegun l’oju ‘ja,
Asegun ‘joba okunkun.

2. mf Egbe ori yin soke,


‘Lekun Pearl at’ita wura,
Wo! Oba nla, Ologo mbo,
Ki keke ogun Re to de:
Tani Oba ogo na?
Tani Oba ogo na?
Oluwa ‘won ‘mogun
Olorun Ologo,
On li Oba ayeraye.

3. On pelu Baba at’Emi,


Won je okan na titi lae,
Awon angeli se l’Oba,
Won nteriba n’waju ‘te Re
On ni Oba ogo na,
On ni Oba ogo na,
Je k’aye juba Re,
K’a si f’iyin wa fun
Titi aye ainipekun.
Amin
134
5.7.6.4. Ref.
Wo o, oko iyawo mbo. Mat. 25:6.

1. Oko ‘yawo de!


‘Yawo Od’aguntan dide
Agbo igbe l’oru
Dide, ye sun!

f Wo! Oko iyawo de


Wo! Oko iyawo de
Wo! Oko iyawo de
Jade lo pade Re

2. mf Ase ‘yawo
Setan, mura sile;
Ki o ba le wonu
Paradise

3. cr Diju s’aye
Ati ona re gbogbo
Dide yara jade
Lo pade Re

4. Dide Korin,
Isegun re bere
A n omije re nu
Banuje tan
. Amin.
135
8.7.8.7.
Kiyesi i, Emi mbo kankan, ere mi si mbe pelu mi. Ifi. 22:12

1. Jesu ti Baba ti gbega


Lat’ipilese aye,
On kanna yio pada wa
Lati se ‘dajo aye.

2 . Wo! Pipada bo Re daju,


A ki y’o ha mura de E?
K’a ba le ni ‘gbala kikun
L’ojo ologo nla ni.

3. Y’O f’ara han l’awosanma,


Gbogbo oju ni y’o ri,
Ati awon t’o kan mo ‘gi
Gbogb’aye ni y’o jiyin.

4. Mo ‘le fi ‘gbagbo so wipe


Un o ba Jesu goke lo,
Si ‘joba egberun odun,
Ati ti ayeraye.

5. Sugbon awon miran ki y’o


Ba Oluwa wa goke,
Nitor’ise won ko lere,
Ti won se l’oj’aye won.

6 . A nreti dide Re sibe,


‘Wo ni ‘reti gbogb’aye
Ma bo, ‘Wo Olugbala wa,
Mu wahala wa d’opin
. Amin.
136
8.7.8.7.
Ki eyin ki o mura sile; nitori ni wakati ti enyin ko ro tele li Omo-eniyan yio de. Mat.
24:44.

1. mf Aye ha nsaferi nipa


Bibo Krist’ nigba keji?
f Bi orun on aye koja,
Oro na ki y’o ye lae.

2. f Gege bi ojo Noa ti ri,


Beni wiwa Omo Eniyan;
‘Torina e je ka mura,
Ki oko ‘yawo to de.

3. Alabukun ni fun eni


Ti Kristi ba ti nsona;
On y’o si fi se olori,
N’nu ‘joba ayeraye.

4. ff A! ayo ojo ajinde!


Ayo na y’o ti po to!
Toko, aya, omo, are,
Yoo maa korin ‘rapada.

5. cr Jesu Oluwa ka wa ye
Si ‘joba ologo yi;
Ka le dapo m’awon t’orun;
Lati ma yin O laelae.
Amin.
137
8.7.8.7.D.
Ife gbogbo orile ede yio si de. Hag. 2:7

1. mf Imole awon t’o joko


Leti ibebe iku,
Wa, jek’itansan ife Re
Tu okunkun aye ka;
Eleda orun on aye,
La si okunkun eda,
Ki aimoye wa le kuro,
Ki oju wa le reran.

2. mf A nreti dide Re sibe,


‘Mole Re fun wa l’ayo
O le gbogbo eru wa lo,
O fi ‘tunu f’okan wa;
Wa, f’oju-‘re Olorun han
Ti O fi ra wa pada;
Wa, Iwo Olugbala wa,
Mu ‘hin-rere wa fun wa.

3. cr Fi iyonu nla Re gba wa,


Olorun alafia;
Jek’a mo adun igbala,
Dari ese wa ji wa,
Fi itoye irapada
Da okan ebi sile;
mf To gbogbo okan ti nsako
Si ona alafia.
Amin.
138
7.7.7.7.
Olorun nikan li okan mi duro je de; lati odo Re wa ni igbala mi. OD. 62:1

1. f ‘Wo Jesu t’a ti nreti


Lati gba wa low’ese,
‘Gbawo ni ‘gbala yo de,
Ti ao da ide ese.

2. mf ‘Wo Olugbala aye,


Wo ‘banuje okan san,
cr Gbe eru wuwo kuro,
M’okan wa yo ninu ‘se Re.

3. mf Awon woli eke po,


Won si nfi ‘se ‘yanu han,
Lati tan ayanfe je;
cr Oluwa da won lekun.

4. Oluwa awa mbe O,


Fun wa l’emi ‘farada,
Lati le sin O d’opin,
Ka ma f’ara fun ‘danwo.

5. mf Mu okan t’o sun soji,


Le ailera wa jinna,
K’a le wa ni isokan
Titi ao fi ri O.

6. f Oluwa Olubukun,
Lodo Re ni ayo wa,
Fun wa l’ore-ofe Re
K’o ma ba wa gbe titi.
Amin.
139
7.7.7.7.D.
Emi o si tun pada. Jn. 14:3.

1. f Iwo mbowa, Oluwa;


Iwo mbowa, Oba mi;
cr Ninu ‘tansan ewa Re,
Ni titayo ogo Re.
Mura dee, e mura dee,
Oko ‘yawo fere de,
L’oru ni igbe y’o ta,
Mura lo ko O, okan mi.

2. mf Wundia t’o s’oloto


Ti mura nigba gbogbo
Igba ayo sunmole,
Igba awe y’o dopin.

3. mf Iwo mbowa nitoto,


A o pade Re lona
A o ri O, a o mo O
N’idapo mimo julo.

4. mf Wundia mewa l’a yan,


Marun pere l’o yege,
mpMarun ko ni ororo,
p Ina emi nwon ti ku.

5. mp‘Binu Re tobi pupo


Si awon t’o gbagbe Re;
Ewure apa osi
L’a o se won nikeyin.

6. mf Jowo se wa l’ayanfe,
Ki a le ba O joba;
Angeli l’ao ba k’egbe
N’gba t’a ba gbe aiku wo
. Amin.
140
L.M.
O mbo, lati se idajo aye. OD. 96:13.

1. f Oluwa mbo; aye yo mi,


Oke y’o sidi n’ipo won;
At’ irawo oju orun,
Y’o mu imole won kuro.

2. f Oluwa mbo; bakanna ko


p Bi o ti wa n’irele ri;
Odo-agutan ti a pa,
pp Eni-iya ti o si ku.

3. f Oluwa mbo; li eru nla,


L’owo ina pelu ija
L’or’ iye apa Kerubu,
Mbo, Onidajo araye.

4. mf Eyi ha li eniti nrin,


Bi ero l’opopo aye?
Ti a se ‘nunibini si?
pp Eni ti a pa l’eyi?

5. mf Ika; b’e wo ‘nu apata,


B’e wo ‘nu iho, lasan ni;
f Sugbon igbagbo t’o segun,
ff Y’o korin pe, Oluwa de.
Amin.
141
8.7.8.7.8.7.
Ji iwo eniti o sun. Efe. 5:14.

1. mf Wo oju sanma ohun ni,


Wo lila orun oro,
f Ji l’oju orun, okan mi
Dide k’o si ma sora!
Olugbala, Olugbala,
Tun npada bo wa s’aye.

2. O pe ti mo ti nreti Re
L’are l’okan mi nduro
Aye ko ni ayo fun mi
Nibiti ko tan ‘mole
Olugbala, Olugbala,
‘Gbawo ni ‘Wo o pada?

3. mf Igbala mi sunm’etile
Oru fere koja na
p Je ki nwa nipo irele
Ki ns’afojusona Re
Olugbala, Olugbala,
Titi un o fi r’oju Re.

4. mf Je ki fitila mi ma jo,
p Ki nma sako kiri mo,
Ki nsa ma reti abo Re
Lati mu mi lo s’ile;
Olugbala, Olugbala,
ff Yara k’o ma bo kankan.
Amin
142
6.6.6.6.8.8.
Oru bukoja tan, ile si fere mo. Rom. 13:12.

1. Oru bu koja tan


Osan ku si dede;
Iboju fere ya
T’o bo Olugbala;
Sanma ti o di wa loju
L’a fere tu kakiri na.

2. f E gb’ori yin soke


Igbala sunmo ‘le,
Wo bi orun ti ran,
Oju orun mole;
ff Eniyan mimo, e si ma yo;
Oluwa fere f’ara han.

3. B’eniyan nrerin yin,


Ti won ko fe gbagbo,
Eyin gb’oro Re gbo,
On ko le tan yin je
Nigbati aye ba koja,
Eyin o ri ogo Re na.

4. Fun yin ni Oluwa,


Pese ile didan;
Ko si ‘kanu nibe
Kik’ayo l’okun ‘be;
mf Eyin mimo, bere si ‘yo,
E fere gbohun Angel’ na.
Amin.
143
C.M.
Kiyesi i, emi mbo kankan. Ifi. 22:7.

1. f Jesu kigbe pe, “Emi de,


T’emi ti ife nla”
Okan mi dahun pe, “Ma bo”,
K’o mu igbala wa.

2. Wa, gba oran Baba Re ro;


Si mu ogo Re ran;
f Wa, ji oku iranse Re,
K’o si so won d’otun.

3. Ma bo wa ‘larin ogun Re
Lati gb’oruko won;
K’o si m’ajo kikun pada
Lati y’ite Re ka.

4. Olurapada, wa kankan,
Mu ojo nla ni wa
mf Wa, k’okan wa ma ba daku,
Nitori pipe Re.
Amin.
144
8.7.8.7.4.7
Wakati mbo, ninu eyiti gbogbo awon ti o wa ni isa oku yio gbo ohun Re, n’won o si jade
wa. Jn. 5:28 - 29.

1. f Ojo ‘dajo, ojo eru!


Gbo bi ipe ti ndun to!
O ju egbarun ara lo
O si nmi gbogbo aye.
p Bi esun na
Y’o ti damu elese!

2. mf Wo Onidajo l’awo wa,


T’o wo ogo nla l’aso.
Gbogbo won ti nwo ona Re,
‘Gbana ni won o ma yo.
p Olugbala,
Jewo mi ni ijo na.

3. f Ni pipe Re o ku o ji
Lat’ okun, ile, s’iye:
Gbogbo ipa aye y’o mi,
Won o salo loju Re.
p Alaironu,
Yoo ha ti ri fun o?

4. mf Esu ti ntan o nisiyi,


Iwo ma se gbo tire,
‘Gbati oro yi koja tan,
Y’o ri o ninu ina;
p Iwo ronu
Ipo re ninu ina!

5. p Labe iponju, at’egan,


K’eyi gba o n’iyanju;
Ojo Olorun mbo tete,
‘Gbana ekun y’o d’ayo,
f A o segun
Gbati aye ba gbina
Amin.
145
S.M.

Gbogbo oju ni yio ri i. Ifi 1:7.

1. Onidajo mbo wa,


Awon oku jinde,
Enikan ko le yo kuro
‘Nu mole oju Re.

2. Enu ododo Re
Yio da ebi fun
Awon t’o so anu Re nu;
Ti won se buburu.

3. “Lo kuro lodo mi


S’ina ‘ti ko l’opin
Ti a ti pese fun Esu
T’o ti nsote si mi”.

4. Iwo ti duro to!


Ojo na o mbo wa,
T’aye at’orun o fo lo
Kuro ni wiwa Re.
Amin.
146
7.7.7.7.
Tani Oba ogo yi? OD. 24:8

1. mf Eyin t’o ngb’oke orun


E so “Ta l’Oba ogo”
Ta l’oga julo nibe?
T’o si l’agbara gbogbo?

2. Od’agutan nikan ni,


L’o pe oye na ni t’On;
On l’o wa lori ite,
On si ni Oba ogo.

3. Ihin nla; Jesu l’Oba,


On nikan l’o si joba;
W’odo Re t’eyin t’ore
E wole niwaju Re.

4. Je k’aye k’o rerin Re,


Je ki won ko lati sin;
Angel’ nyo l’oruko Re,
Gbogbo eda orun nsin.

5. A yin O, ‘Wo t’Angel’ n sin


Od’Agutan Olorun,
Ma joba titi laelae,
Oba ye O, Oluwa.
Amin.
147
C.M.
E pese okan nyin sile. I Sam. 7:3.

1. f Jesu t’o ga julo l’orun,


Ipa Re l’o d’aye;
‘Wo f’ogo nlanla Re sile,
Lati gba aye la.

2. O w’aye ninu irele


mf Ni ara osi wa;
p Nitori k’okan t’o rele
Le t’ipase Re la.

3. f Wiwa Re ya angel’ l’enu,


Ife t’o tobi ni;
Eniyan l’anfani iye
Angeli se, ko ni.

4. f Nje araye yo; sa yin de,


ff E ho iho ayo:
Igbala mbo fun elese;
Jesu, Olorun ni.

5. Oluwa, je ki bibo Re,


Nigba erinkeji,
Je ohun ti nduro de,
K’o le ba wa l’ayo.
Amin.
148
8.8.8.6.8.8.8.8.& Ref.
Ogo ni fu Olorun loke orun. Lk. 2:14.

1. f Ogo f’Olorun lok’orun,


Ogo; ogo ni f’Olorun
Ogo f’Olorun lok’orun,
Li orin wa loni
Orin ti owuro ayo
Ti a bi Omo Dafidi
Ti ogun orun ko; awa
Si fe dapo mo ogun na.
Ogo f’Olorun lok’orun,
Ogo f’Olorun lok’orun,
Ogo, ogo, ogo, ogo,
Ogo f’Olorun loke.

2. f Ogo f’Olorun lok’orun,


Ogo; ogo ni f’Olorun
Ogo f’Olorun lok’orun,
Li orin wa loni
Anu ti a nri gba fi han
Bi ife Re ti tobi to
Je ki a gb’ohun wa soke
Korin iyin Olugbala.

3. f Ogo f’Olorun lok’orun,


Ogo; ogo ni f’Olorun
Ogo f’Olorun lok’orun,
Li orin wa loni.
p Je ki awa le duro pe
Niwaju ‘te Olugbala
K’a korin pel’awon angel’,
At’awon eni ‘rapada
. Amin.
149
10.10.10.D.
Sa wo o, mo mu ihinrere ayo nla fun yin wa. Lk. 2:10.

1. f Ji, ‘wo Kristian, k’o ki oro ayo


Ti a bi Olugbala araye;
Dide, k’o korin ife Olorun
T’awon Angeli nko n’ijo kini;
Lat’odo won n’ihin na ti bere;
I hin Om’Olorun t’a bi s’aye.

2. mf ‘Gba na l’a ran akede angeli;


T’a so f’awon olus’agutan pe,
“Mo mu ‘hinrere Olugbala wa
T’a bi fun yin ati gbogbo aye,
Olorun mu leri Re se loni
A bi Olugbala, Krist’Oluwa.

3. mf Bi akede angel’ na ti so tan,


Opolopo ogun orun si de;
Won nkorin ayo t’eti ko gbo ri,
Orin Aleluya gba orun kan,
Ogo f’Olorun l’oke orun,
Alafia at’ife s’eniyan.

4. A ba le ma ranti nigbagbogbo
Pe, ‘fe Olorun l’o gba ‘raye la,
K’a to ‘se Jesu t’o ra wa pada,
Lat’ibuj’eran de or’agbelebu;
K’a toro or’-ofe k’a le te le,
Titi a o tun r’oju Re Olorun.

5. f Nigbana ‘gba ‘ba de orun lohun;


A o korin ayo t’irapada;
Ogo Eni t’a bi fun wa loni,
Y’o ma ran yi wa ka titi laelae;
A o ma korin ife Re titi,
Oba angeli, Oba eniyan.
Amin.
150
8.7.8.7.4.7.
Awa si wa lati f’ori bale fun. Mat. 2:2

1. f E yin angel’ l’orun ogo,


To yi gbogbo aye ka;
E ti korin dida aye,
E so t’ibi Messaiah
f E wa josin
Fun Kristi Oba titun

2. mf Eyin Oluso-aguntan
Ti nso eran yin l’oru,
Imanueli wa ti de,
Irawo Omo na ntan.

3. Amoye, f’ero yin sile,


Wo ‘ran didan lokere!
Wa ‘reti nla orile’ de,
E ti ri irawo Re.

4. mf Onigbagbo ti nteriba
Ni ‘beru, at’ireti,
L’ojiji l’Oluwa o de
Ti yio mu yin re ‘le.

5. A nwo b’om’owo nisi’yi,


Y’o gba ite Baba Re,
Ao ko gbogb’aye s’odo Re,
Gbogb’ekun yo wole fun.
Amin.
151
7777.7777.77
Nitori a bi omo kan fun wa a fi omokunrin kan fun wa.
Isa. 9:6.

1. f Gbo eda orun nkorin:


“Ogo fun Oba t’a bi”
p “Alafia l’aye yi”
cr Olorun ba wa laja,
f Gbogbo eda nde l’ayo,
E gberin, at’oke wa,
Kede pel’angeli pe
A bi Kristi in Betlehem’
Gbo eda orun nkorin
Ogo fun Oba t’a bi.

2. Kristi t’a nyin l’ogo l’orun,


Kristi Oluwa titi lae,
Ni igbeyin, wo, o de,
Omo inu wundia!
W’Olorun di eniyan!
Olorun di eniyan
O dun mi k’o b’eeyan gbe
Jesu, Imanuel’ wa.

3. Wo, Alade alafia!


Wo o, orun ododo!
O mu ‘mole iye wa,
‘Lera mbe li apa re,
O bo ‘go re s’apakan,
A bi k’eniyan ma ku;
A bi ko gb’eniyan ro,
A bi k’o le tun won bi.

4. Wa ‘reti oril’ede,
F’okan wa se ‘bugbe Re,
Nde, Iru Omo ‘birin,
Segun esu ninu wa,
Pa aworan Adam re,
F’aworan Re dipo re,
Adam’ ‘keji lat’oke,
Gba wa pada s’ife re.
Amin.
152
C.M.
Oluwa joba. OD. 97:1.

1. f Ayo b’aye! Oluwa de,


K’aye gba Oba re?
cr Ki gbogbo okan mura de,
K’aye korin s’oke.

2. f Ayo b’aye! Jesu joba,


cr E je k’a ho f’ayo,
Gbogbo igbe, omi, oke,
Won ngberin ayo na.

3. mf K’ese on ‘yonu pin l’aye,


K’egun ye hu n’ile,
O de lati mu ‘bukun san,
De ‘bi t’egun gbe wa.

4. O f’oto at’ife joba,


O je k’orile’de
Mo, ododo ijoba Re,
At’ife ‘yanu Re.
Amin.
153
C.M. & Ref.
A o ma pe oruko re ni Imanueli. Mat. 1:23.

1. f Ayo kun okan wa l’oni,


Abi omo Oba!
Opo awon ogun orun
Nso ibi re loni!
ff E yo, Olorun d’eniyan
O wa joko l’aye!
Oruko wo l’o dun to yi
Imanuel’

2. mp A wole n’ibuje eran,


N’iyanu l’a josin,
cr Ibukun kan ko ta yi yo,
Ko s’ayo bi eyi.

3. mf Aye ko n’adun fun wa mo


‘Gbati a ba now O
L’owo wundia iya Re,
‘Wo Omo iyanu.

4. f Imole lat’inu ‘Mole,


Tan ‘mole s’okun wa!
K’a le ma fi isin mimo
Se ‘ranti ojo Re.
Amin.
154
6.6.10.5.6. & Ref.
E je ki a lo tara si Bethlehem. Lk. 2:15.

1. f Wa eyin olooto!
L’ayo at’isegun,
Wa ka lo, wa ka lo si Betlehem
Wa kalo wo o
Oba awon Angel’
f E wa kalo juba Re
E wa kalo juba Re
E wa ka lo juba Kristi Oluwa.

2. Olodumare ni
Imole ododo,
p Ko si korira inu wundia
f Olorun papa
Ti a bi, t’a ko da!

3. Angeli, e korin
Korin itoye Re!
Ki gbogbo eda orun si gberin,
Ogo f’Olorun
L’oke orun lohun!

4. f Nitoto a wole
F’Oba t’a bi loni,
Jesu Iwo li awa nf’ogo fun!
‘Wo Omo Baba,
T’o gbe ara wa wo!
Amin.
155
8.7.8.7.
Iwo Betlehemu, Iwo ko kere julo nin’awon omo alade Juda. Mat. 2:6.

1. f Ilu t’o dara po l’aye


Betlehem’, ‘wo ta won yo,
Ninu re l’Oluwa ti wa
Lati joba Israel’.

2. Ogo ti irawo ni ju
Ti orun owuro lo,
Irawo t’o kede Jesu
Ti a bi ninu ara,

3. Awon ‘logbon ila-orun


Mu ‘yebiye ore wa;
E wo bi won ti fi wura,
Turari, ojia fun.

4. Awon ebun iyebiye;


Turari, nf’okan s’oke,
Wura won nkede Oba won,
Ojia nfi ‘boji Re han.

5. Jesu, ‘Wo ti keferi nsin


Li ojo ifihan Re;
Fun O, Baba l’a f’ogo fun
Ati fun Emi Mimo.
Amin.
156
7.7.7.7.7.7.
Nigbati nwon si ri irawo na, nwon yo ayo nlanla. Mat. 2:10.

1. f B’awon ara igbani


Ti f’ayo ri ‘rawo na,
Bi won ti f’inu didun
Tele ‘mole didan re,
Be, Oluwa Olore
Ni k’a mu wa d’odo Re.

2. mf Bi won ti fi ayo lo
Si ibuje eran na,
Ti won si wole nibe,
F’Eni t’orun t’aye mbo,
Gege be ni k’a ma yo
Lati wa site anu.

3. Bi won ti mu ore wa
Si ibuje eran na,
Be ni k’a f’ayo mu wa
Ore t’ese ko baje,
Mu isura gbogbo wa
Sodo Re, Jesu Oba.

4. p Jesu mimo, pa wa mo
L’ona toro l’ojojo
cr ‘Gbat’ohun aye ba pin
M’okan wa de ilu, ti
f ‘Rawo ko nsamona mo,
‘Biti won now ogo Re.

5. ff Ni ‘lu orun mimo na,


Won ko wa imole mo,
‘Wo l’orun re ti ki wo,
‘Wo l’ayo at’ade re,
Nibe titi l’ao ma ko
Aleluya s’Oba wa
. Amin.
157
C.M
Nitori a bi Olugbala fun yin loni ni ilu Dafidi, ti ise Kristi Oluwa. Lk. 2:11.

1. Bi awon Olus’agutan
Ti ns’agbo won l’oru;
Angel’ Oluwa sokale,
Ogo ran yin wonka.

2. Eru ba won pupo, sugbon


O ni - “E ma beru,
Ihin ayo ni mo mu wa
Fun yin at’araye,”

3. Fun yin n’ilu Dafid’, loni,


N’idile Dafidi,
A bi Olugbala ti se
Kristi, Oluwa wa;

4. Eyi ni y’o j’ami-Eyin


O ri om-owo na,
A fi oja we, a si te
Si ibuje eran.

5 . Bi angel’ na ti soro tan


Opo awon angel’
Fo de, won si nyin Olorun
Won nkorin ayo pe

6 . Ogo ni f’Olorun loke


Alafia l’aye,
K’ife ‘nurere s’eniyan
Bere, laini opin.
Amin.
158
8.7.8.7.D.
A bi Olugbala fun yin loni ti ise Kristi Oluwa. Lk. 2:11.

1. A f’ope fun Olorun wa


To ran Omo Re w’aye;
K’ayo gba gbogbo aye kan
F’omo na t’a bi loni.
E ho, eyo, gbogb’eniyan,
E fiyin f’Olorun wa,
E ho, eyo, onigbagbo;
K’iyin gba okan wa kan.

2. A fope fun Olorun wa


Fun ‘fe nla to ni si wa;
O ran Olugbala w’aye,
Lojo oni awa nyo.

3. Ki gbogb’eso inu igbo,


Koko, ope on roba,
Gbogbo isura ‘nu ile
Ba wa f’iyin f’Oba wa.

4. Je ki eja inu ibu


At’ eye oju orun,
Ki gbogbo eranko igbe,
Wa f’iyin f’Oluwa wa.

5. Bi a ti nse ti odun yi,


A mbe O, Metalokan,
Jek’a le wa f’iyin fun O
Niwoyi odun to mbo
. Amin.
159
10.8.10.8.
Gbogbo ahon ni ki o ma jewo pe, Jesu Kristi ni Oluwa. Fili. 2:11.

1. Omo n’bujeran l’omo Maria,


Alejo, Oluwa aye,
Omo to ru gbogbo asise wa
Ati awon abuku wa.

2. Nigbakan l’omo Mimo julo yi


F’irele gbe ‘nu aye yi;
Nisiyi gege b’Olurapada
O ni ‘segun lori ota.

3. Awon woli so asotele re;


Awon angel ri lor’ite
Olugbala, ‘Wo ni iyin ye fun;
Layo l’awon Tire y’o wa.
Amin.
160
8.7.8.7.
Ati li aye alafia; ife inu rere si eniyan. Lk. 2:14.

1 . Alafia f’aye at’eeyan


L’orin t’awon angel’ ko;
Awon Olus’agutan gbo
T’Ikede ibi Kristi.

2. Ni ori oke Judea


N’imole ‘rawo nla tan
Lati s’amona fun awon
Ti nwa ebun ‘yanu yi.

3. Awon amoye meta ni


Ri imole nlanla na;
Won mu ebun wa f’omo na,
Wura, turari, ojia.

4 . Leba ibuje eran na


Won juba fun Oba won,
N’irele won f’ebun lele
F’eni to mu ‘gbala wa.

5. Bi odun ti nyi lu odun


L’a tun nbi Krist’ ni titun
N’nu okan aawon omo Rre,
B’angeli ti so tele.

6. A nri ‘rawo na nisiyi


B’akoko ta bi Kristi;
Ki ‘bukun Kristi je tire
B’odun ti nyi lu odun
. Amin
161
C.M.
Lati wasu ihinrere fun awon otosi, lati se awotan awon
onirobinuje okan, lati kede idasile fun awon igbekun.
Isa. 61:1.

1. Gbo iro orin angeli


Ti ndun yi aye ka;
A bi Olugbala s’aye
Om’Olorun d’eniyan.

2. A bi Olugbala loto
Fun gbogbo agbaye;
Lati da wa n’de low’esu
Kuro ninu egbe.

3 . Opo ogun orun si yo


Fun ‘Mole to de yi,
Ogo f’Olorun lok’orun,
Alafia f’eniyan.

4. A ha mo b’o ti soro to
Lati f’ite sile,
Lati mu ago kikoro
Fun ‘rapada en’yan!

5 . E fi ope fun Olorun


Fun ife nlanla yi
To ran Omo Re kansoso
Wa s’aye osi yi.

6. ‘Wo Omo na t’a bi loni


F’alafia fun aye,
F’ore-ofe Re ba wa gbe
At’ayo ibi Re.
Amin.
162
6.6.8.6.6.8.
Nwon si wa logan, nwon si ri omo owo na, O dubule ninu ibuje eran. Lk. 2:16.

1. Eyin onirele,
Ayaro, amukun,
E sare wa, mase beru;
Jesu isura wa,
T’ife Re ko n’iwon,
Ni ibujeran l’a te si.

2. B’awon amoye ni
Tile f’ebun nla fun
Awon malu pelu si fun
Ni koko fun ‘busun’
Jesu gba ore won
N’itelorun n’ibujeran.

3. E yara, jek’a lo
San gbese ‘yin wa fun;
Iisin wa ni On ki yo gan;
Eni ti ife Re
Si le s’amona wa
S’ibujeran ti a te si
. Amin.
163
11.10.11.10.
Awa ti ri irawo Re ni ila-orun, awa si wa lati foribale fun u.Mat. 2:2.

1. mf Irawo owuro Ologo julo,


Tan si okunkun wa, ran wa lowo;
Irawo ti ns’amona ero l’ona,
Sin wa de ibi t’Olugbala wa.

2. mp O dubule jeje ni ibusun Re,


A te sile larin awon eran;
Awon angeli njuba Re b’O ti nsun,
Eleda, Oba, Olugbala wa.

3. mf Ko ha ye k’a mu ore didun wa fun;


Orun didun t’o nta sansan t’Edomu’,
Isura lat’oke, pearli lat’okun,
Ojia lat’igbo, wura inu ‘le.

4. mp Lasan n’isura je, lasan l’ebun wa,


B’a ko ba sin l’emi at’otito
mf ‘Yebiye loju Re b’a f’okan wa fun;
cr Owon julo l’adura otosi.

5. mf Irawo Owuro Ologo julo,


Tan si okunkun wa, ran wa lowo;
Irawo ti nsamona ero l’ona,
Sin wa de ibi t’Olugbala wa
. Amin.
164
8.7.8.7.8.7.
Awa o ma yo, inu wa yio si ma dun. OD. 118:24.

1. f Onigbagbo, e bu s’ayo
Ojo nla l’eyi fun wa;
E gbo bi awon Angeli
Ti nf’ogo fun Olorun
Alafia, alafia
Ni fun gbogbo eniyan.

2. ff Ki gbogbo aye ho f’ayo


K’a f’ogo fun Olorun
Omo bibi Re l’o fun wa
mf T’a bi ninu Wundia:
Eni iyanu, En’iyanu
Ni omo t’a bi loni.

3 f Ninu gbogbo rudurudu


On ibi t’o kun aye,
Ninu idamu nla ese
L’om’Olorun wa gba wa;
Olugbimo, olugbimo,
Alade Alafia.

4. f Olorun Olodumare
L’abi, bi omo titun:
Baba! Eni ayeraye
L’o di alakoso wa;
ff E bu s’ayo, E bu s’ayo
Omo Dafidi ‘joba.

5. p O wa gba wa lowo ese


O wa d’onigbowo wa
Lati fo itegun Esu,
A se ni Oba ogo:
f E ku ayo, Eku ayo
A gba wa lowo iku.
Amin
165
8.7.8.7.8.7.
A wa si wa foribale fun. Mat. 2:2

1. ff Onigbagbo, e bu s’ayo
Ojo nla l’eyi fun wa;
K’orin f’ayo korin kikan
K’igbo at’odan gberin
ff E ho! e yo! E ho! eyo!
Okun at’odo gbogbo.

2. f E jumo yo, gbogbo eda,


Laye ati lorun
f Ki gbogbo ohun alaaye
N’ile loke yin Jesu
E f’ogo fun, E f’ogo fun
Oba nla t’a bi loni!

3. ff Gb’ohun yin ga, “Omo Nigeria”


Eyin iran Yoruba
Ke “Hosanna?” l’ohun goro
Jake-jado ile wa
K’oba gbogbo, k’oba gbogbo
Juba Jesu Oba wa

4. f E damuso! e damuso!
ff E ho ye! k’e si ma yo
Itegun esu fo wayi,
“Iru-omobinrin” de!
Aleluya! Aleluya!
Olurapada, Oba .

5. E gb’ohun yin ga, El-shaddai


Kerubu, leba ite;
Angeli at’eyin mimo
Pelu gbogbo ogun orun,
f E ba w ayo! E ba wa yo!
Odun idasile de .

6. Metalokan, Eni Mimo


Baba, Olodumare
Emi Mimo, olutunu,
Jesu, olurapada
Gba iyin wa, Gba iyin wa,
‘Wo nikan l’ogo ye fun.
Amin
166
L.M.
Mo mu ihin ayo nla fun nyin wa. Lk. 2:10.

1. f Ojo ayo nlanla na de,


Eyi t’araye ti nreti;
cr Nigbat’ Olugbala w’aye
Nigbat’ a bi ninu ara.

2. f Olus’agutan ni papa
Bi won ti nso agutan won,
Ni ihin ayo na ko ba.
Ihin bibi Olugbala.

3. Angel’ iranse Oluwa


L’a ran si won, alabukun,
Pelu ogo t’o tan julo,
Lati so ihin ayo yi.

4. mp Gidigidi l’eru ba won,


Fun ajeji iran nla yi;
f “Ma beru” l’oro iyanju
T’o t’enu Angeli na wa.

5. A bi Olugbala loni,
Kristi Oluwa aye ni;
N’ilu nla Dafidi l’o wa,
p N’ibuje eran l’a te si.

6. f “Ogo fun Olorun” l’orin


Ti eniyan y’o ko s’orun:
Fun ife Re laini opin,
T’o mu alafia w’aye. Amin.
167
7.6.7.6.D.
Olorun si li Oro na, Oro na si di ara. Jn. 1:1, 14.

1 mf E ji, eyin eniyan


E ma se sun titi;
f A! Imole wa nlanla
On li o yo de yi
Orun n’imole ara,
Jesu ni ti okan?
Ireti awon baba
Yio ha de lasan?

2. p O de k’ewon ese tu
O de k’okunkun lo;
f E yo, ijoba Jesu
O ni rorun pupo,
E je k’a mu ore wa
K’a juba Oba wa
Awon amoye mu wa
A ki o mu wa bi?

3. f Je k’a fi okan wa fun,


K’o te ‘te Re sibe;
K’a fi ohun gbogbo fun
K’a si se ife Re
ff E yo! E yo! e tun yo!
Jesu Oluwa de
F’otosi at’oloro,
Kristi Oluwa de.
Amin.
168
7.7.7.7.
Ogo ni fun Olorun loke orun. Lk. 2:14.

1. f ‘Gba Jehofa da aye,


cr ‘Gbat’o soro t’o si se,
Awon Angeli nkorin
ff Aleluya gb’orun kan.

2. mf Orin ‘yin l’a ko l’oro


Gbat’a bi Olugbala;
cr Orin ‘yin ni a si ko
Nigbat’o digbekun lo.

3. p ‘Gbat’aye y’o koja lo,


Iyin o gb’ojo na kan;
‘Gbat’a o d’aye titun,
Orin iyin l’a o ko.

4. Awa o ha dake bi
Titi joba na o de?
Beko! Ijo o ma ko
Orin mimo at’iyin.

5. Eniyan mimo l’aye,


Nf’ayo korin iyin na;
Nipa ‘gbagbo ni won nko,
Bi won o ti ko l’oke.

6. p Nigba emi o ba pin


Orin ni o segun ‘ku;
f Ninu ayo ailopin
Won o ma korin titi.
Amin.
169
8.7.8.7.
Angeli na si dahun o si wi fun u pe, Emi Mimo yio to o wa
, ati agbara Oga-Ogo yio siji bo o: nitorina ohun Mimo ti a o ti inu re bi,
Omo Olorun li a o ma pe e. Lk. 1:35.

1. f Ma wo ‘le, Jesu t’a nreti,


T’a bi lati gba ni la!
cr Gba wa low’ese at’eru;
p K’a r’isimi ninu Re.

2. mf Ipa at’itunu Israel’;


Ireti awon mimo;
Olufe gbogbo orile,
Ayo okan ti nreti.

3. mf A bi O lati gb’eda la,


Eniyan-sugbon Olorun
Lati joba lae ninu wa.

4. mpNipa Emi Re t’o wa lae,


Nikan joba ninu wa;
Nipa ‘toye Re t’o po to,
Gbe wa s’ite ogo Re
. Amin.
170
7.7.7.7.
Omo Alade Alafia. Isa. 9:6.

1. O de, Kristi Oluwa,


Lat’ibugbe Re l’orun,
Lat’ite alafia,
O wa si aginju wa.

2. Alade Alafia
De, lati ru ‘ponju wa,
O de, lati f’imole
Le okun oru wa lo
. Amin.
171
7.5.7.5.D.
Ki a le ma yin Olorun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi. I Pet. 4:11.

1. mf Baba je nya Odun yi


Si mimo fun O,
N’ipokipo t’o wu O
Lati fi mi si,
Nko gbodo ko ‘banuje
Tabi irora,
Eyi sa l’adura mi,
Ogo f’oko Re.

2. mf Om’owo ha le pase
Biti on y’o gbe?
Ife Baba le du ni
L’ebun rere bi?
‘Jojumo n’Iwo nfun wa
Ju b’a ti bere,
Laidu wa l’ohun t’o le
Gbe oko Re ga.

3. cr Ninu anu, b’Iwo ba


Fun mi, li ayo,
T’o je k’ewa aye mi
Tubo tan jade,
Je k’okan mi ma f’ayo
Korin iyin Re,
Ohun t’ola ba mu wa,
“Ogo f’oko Re”.

4. p B’O mu ‘ponju wa ba mi
T’ona mi s’okun
T’ere mi di adanu,
Ti ile mi kan;
Je ki nranti bi Jesu
Se de ‘nu ogo,
Ki ngbadura n’nu ‘ponju,
mf “Ogo f’oko Re”.
Amin.
172
D.S.M.
Nigba die ewe, e o si ri mi. Jn. 16:16.

1. mpLeyin odun die,


Leyin igba die,
di A o ko wa jo pel’awon
p To lo silu ogo
cr Oluwa, mu mi ye
Fun ojo nlanla na;
Jo, we mi ninu eje Re
p Si ko ese mi lo.

2. mpLeyin ojo die


L’aye okunkun yi,
di A o de ‘bi orun ko si mo,
Ile daradara.

3. mpLeyin iji die,


L’ebute giga yi,
di A o de b’igbi ko si mo,
Ti irumi ko si

4. mpLeyin ‘yonu die,


Leyin ‘pinya die,
di Leyin ise on omije,
A ki o sokun mo.

5. mf Ojo ‘simi die,


L’a ni tun ri l’aye,
mpA o de ibi isimi
Ti ki o pin laelae.

6. f Ojo die l’o ku,


On o tun pada wa,
mf Eniti O ku, k’awa le pe
K’a ba le ba joba.
Amin.
173
C.M.
Igba mi mbe li owo Re. OD. 31:15.

1. mf Igba mi d’owo Re,


Mo fe k’O wa nibe;
Mo f’ara, ore, emi mi
Si abe iso Re.

2. mpIgba mi d’owo Re
Eyi t’o wu k’o je,
Didun ni tabi kikoro,
B’O ba ti ri p’o to.

3. Igba mi d’owo Re,


Emi y’o se beru?
p Baba ki o jek’omo Re
Sokun li ainidi.

4. mf Igba mi d’owo Re,


Jesu t’a kan mo ‘gi;
p Owo na t’ese mi dalu
Wa di alabo mi.

5. f Igba mi d’owo Re,


‘Wo ni ngo gbekele,
Leyin iku, low’ otun Re
L’em’ o wa titi lae
. Amin.
174
7.6.7.6.D.
Bakanna ni Iwo, odun Re ko lopin. OD. 102:27.

1. Apata ayeraye,
Enit’o mbe laelae
Nigbakugba t’iji nja,
‘Wo ‘bugbe alafia:
Saju did’aye wa yi
Saju did’aye wa yi
Iwo, mbe; bakanna
Tit’aye ainipekun
Ayeraye ni ‘Wo.

2. Oj’odun wa ri b’oji
T’o han l’ori oke;
Bi koriko ipa ‘do,
T’o ru ti o si ku:
Bi ala tabi b’itan
T’enikan nyara pa:
Ogo ti ko ni si mo,
Ohun t’o gbo tan ni.

3. ‘Wo eniti ki togbe,


‘Mole enit’itan
Ko wa bi a o ti ka
Ojo wa k’o to tan;
Je k’anu Re ba le wa
K’ore Re po fun wa;
Si je k’Emi Mimo Re
Mole si okan wa.

4. Jesu, f’ewa at’ore


De ‘gbagbo wa l’ade,
Tit’a o fi ri O gbangba
Ninu ‘mole laaelae
Ayo t’enu ko le so,
Orisun akunya;
Alafia ailopin,
Okun ailebute.
Amin.
175
8.7.8.7.
Ko wa lati ma ka iye ojo wa, ki a le fi okun wa sipa ogbon. OD. 90:12.

1. mf Ojo ati akoko nlo;


Won nsun wa s’eti ‘boji
p Awa fere dubule na,
Ninu iho ‘busun wa.

2. mf Jesu ‘Wo Olurapada


Ji okan t’o ku s’ese:
cr Ji gbogbo okan ti nto gbe
Lati yan ipo iye.

3. mp Bi akoko ti nsumo ‘le


Je k’a ro ‘biti a nlo
Bi lati r’ayo ailopin,
pp Tabi egbe ailopin.

4. mf Aye wa nlo, iku de tan


pp Jesu so wa di abo Re,
mf K’a ba O gbe, K’a ba O ku,
pp K’a ba O joba titi.

5. mpAye wa nkoja b’ojiji


O si nfo lo bi ‘kuku,
cr Fun gbogbo odun t’o koja
Dariji wa, mu wa gbon.

6. mf Ko wa lati ka ojo wa,


Lati ba ese wa ja,
K’a ma s’are k’a ma togbe
Tit’a o fi ri ‘simi.

7. f Gbogbo wa fere duro na


Niwaju ite ‘dajo
ff Jesu ‘wo t’o segun iku
Fi wa s’apa otun Re.

8. mf Aye wa nlo, iku de tan


pp Olugbala, pa wa mo,
K’a ba O gbe, k’a ba O ku
f K’a ba O joba titi.
Amin.
176
C.M.
Oluwa, Iwo li o ti nse ibujoko wa lati irandiran. OD. 90:1.

1. f Olorun t’odun t’o koja


Iret’ eyi ti mbo;
Ib’isadi wa ni iji
A t’ile wa laelae.

2. mpL’abe ojiji ite Re


L’awon eniyan Re ngbe,
f Tito l’apa Re nikanso,
Abo wa si daju.

3. mf K’awon oke k’o to duro,


Tabi k’a to d’aye,
f Laelae Iwo ni Olorun
Bakanna, l’ailopin!

4. Egberu odun l’oju Re


Bi ale kan l’o ri;
B’iso kan l’afemojumo
Ki orun k’o to la.

5. Ojo wa bi odo sisan,


Opo l’o si ngbe lo;
Won nlo, won di eni ‘gbagbe
Bi ala ti a nro.

6. f Olorun t’odun t’o koja,


Iret’ eyi ti mbo,
Ma s’abo wa ‘gba ‘yonu de
At’ ile wa laelae.
Amin.
177
C.M.
Nje Oluwa ni yio ma se Olorun mi.
Gen. 28:21.

1. mf Olorun Betel’ eni ti


O mbo awon Tire,
Enit’ o mu baba wa la
Ojo aye won ja.

2. p A mu eje at’ebe wa
Wa iwaju ‘te Re,
Olorun awon baba wa
f Ma je Olorun wa.

3. Ninu idamu aye yi


Ma to isise wa,
Fun wa ni onje ojo wa
At’aso t’o ye wa.

4. Na ojiji ‘ye Re bo wa
Tit’ajo wa o pin
Ati ni ‘bugbe Baba wa,
Okan wa o simi.

5. Iru ibukun bi eyi


L’a mbere l’owo Re,
Iwo o je Olorun wa.
At’ipin wa laelae
. Amin.
178
11.11.11.11 & Ref.
Iwo ma beru, nitori mo wa pelu re.
Isa. 41:10.

1. mf N’ibere odun yi, odun titun yi


Oro itunu de, ti nle eru lo
p Ohun keje jeje, ti Baba orun
cr Ododo l’oro na, ti nm’okan wa ye
f E ma tesiwaju, omo imole,
Oro Re ko le ye, O nduro titi.

2. f “Ma beru” l’oro na, “Mo wa pelu yin”


Emi n’iranwon yin at’agbara yin,
Emi y’o di yin mu, li owo-’tun mi
Mo pe yin, mo yan yin, lati je temi.

3. f Fun opo odun ti mbe niwaju wa,


Opo ni ipese t’o ti seleri:
Ipese f’alaini, f’awon elese,
F’awon t’a npon loju, fun alailera.

4. mf Ko je fi wa sile, ko si ni ko wa,
Majemu Re daju ti ko le ye lae
ff A ro mo ‘leri yi, eru ko ba wa,
Olorun wa ti to, fun odun ti mbo.
Amin.
179
8.7.8.7.4.7.
Olorun si wipe, ... ki nwon ma wa fun ami, akoko ojo ati fun odun. Gen. 1:14.

1. f Oluwa alafia wa
L’O pase t’odun yipo;
Awa omo Re wa dupe
F’ odun tuntun t’ a bere.
Yin Oluwa!
Oba nla t’O da wa si.

2. mf A dupe fun ipamo wa


Ni odun ti o koja;
A mbebe iranlowo Re
Fun gbogbo wa l’odun yi.
Je k’Ijo wa
Ma dagba ninu Kristi.

3. f K’agba k’o mura lati sin


L’okan kan ni odun yi;
K’awon omode k’o mura
Lati s’aferi Jesu.
K’alafia
K’o se ade odun yi.

4. f K’Emi Mimo lat’oke wa


Ba le wa ni odun yi;
Ki Alufa at’Oluko,
Pelu gbogbo Ijo wa
Mura giri
Lati josin f’Oluwa
. Amin
180
7.7.7.7. D
Kili emi nyin? Jak. 4:15.

1. mf Odun miran ti koja


Wawa l’akoko na lo
Ninu eyi t’a wa yi
p Yio s’arimo opo;
Anu l’o fi da wa si,
A ha lo anu na bi?
K’a bi ‘ra wa ba se tan?
B’a o pe wa l’odun-ni.

2. f Aye bi ibi ija,


Egbegberun l’o nsubu;
mf Ofa iku t’o si nfo,
A le ran s’emi b’iwo;
Nigb’a nwasu t’a si ngbo,
Oluwa je k’a saro
P’ayeraye sunmole
A nduro l’eti, bebe.

3. f B’a gba wa lowo ese


Nipa ore-ofe Re,
Nje ‘ma bo’ n’ipe o je,
K’a le lo, k’a r’oju Re:
F’eniyan Re l’aye yi
K’anu wa l’odun titun;
Odun t’o l’ayo ju yi,
L’eyi t’o mu won de ‘le.
Amin.
181
C.M.
Je ki ise Re ki o han si awon omo-odo Re. OD. 90:16.

1. mf Olorun at’ ireti mi,


Oro Re l’onje mi,
Owo Re gbe mi ro l’ewe
Ati l’odomode.

2. Sibe mo nrohun iyanu


T’O nse ni ododun;
Mo fi ojo mi ti o ku
S’iso Tire nikan.

3. Ma ko mi, nigba ‘gbara ye,


Ti ewu ba bo mi,
ff Ki ogo Re ran yi mi ka
p Nigbati mo ba ku.
Amin.
182
7.7.7.7.
Alaye, alaye on ni yio yin O, bi mo ti nse loni yi. Isa. 38:19.

1. mf B’orun l’aiduro ti rin,


La odun ti o lo ja,
Be l’opo ti dopin won
A ki o si ri won mo.

2. A so won l’ojo laelae


Tiwon pari li aye;
Awa nduro die na,
Y’o ti pe to, a ko mo.

3. f Gb’ope f’anu t’o koja,


p Tun dari ese ji wa;
Ko wa b’a ti wa, k’a maa
Se ‘ranti aye ti mbo.

4. f Bukun f’ewe at’agba,


F’ife Oluwa kun wa;
‘Gba ojo aye wa pin
K’a gbe odo Re l’oke.
Amin.
183
D.L.M.
O si pe oruko re ni Ebeneseri wipe: Titi de ihin li Oluwa ran wa lowo. I Sam. 7:12.

1. mf Oluwa at’igbala wa,


Amona at’agbara wa,
L’o ko wa jo l’ale oni,
Je k’a gbe Ebeneser ro;
Odun t’a ti la koja yi,
Ni on f’ore Re de l’ade,
Otun l’anu Re l’owuro;
Nje ki ope wa ma po si!

2. mf Jesu t’o joko lor’ite,


L’a fi Aleluya wa fun;
Nitori Re nikansoso
L’a da wa si lati korin;
Ran wa lowo lati kanu
Ese odun t’o ti koja;
Fun ni k’a lo eyi ti mbo,
S’iyin Re, ju odun t’o lo.
Amin.
184
6.5.9.14.9 & Ref.
Mu mi mo ona ti emi iba ma to OD. 143:8

1. mf Oluwa fi apa Re han


Si je k’ar’ ogo Re,
Ki gbogbo wa ri ami Re,
K’o m’okan lile ro.

2. di K’aanu yo wa ninu ebi


Gbogb’ese t’a ti da,
Ki odun ti a bere yi,
Le pari pelu Re.

3. p Ran Emi Re lat’ oke wa,


K’a le fe O julo,
K’elese ti ko n’ife ri,
Le ko lati feni.

4. mp Nigbat’ a ba de ‘waju Re,


N’ile ayeraye,
f Ki opo d’ipo wa nihin,
Lat f’iyin fun O
. Amin.
185
L.M.
E fi iyin fun Oluwa. OD. 106:1.

1. mf A yin O, Oluranwo wa,


T’ife Re wa bakanna lae,
Owo ike en’ t’o bere,
Ti o si pari odun wa.

2. mf Larin egbegberun ‘danwo,


A duro nipa ‘toju Re;
Nigbat’ a si bojuw’ eyin
A r’ opo ohun fun iyin.

3. mf De ‘hin li apa Re sin wa,


De ‘hin l’a rohin anu Re;
di ‘Gbati a nrin l’asale yi,
Anu bere orin titun.

4. mf Gb’okan wa gunle Jordani,


Won o tun gbe opo kan ro,
Gba won ba si d’agbala Re,
Won o gb’ am’ ife ti ki ku.
Amin.
186
C.M.
Olorun si wipe, ki imole ki o wa l’ofurufu fun ami,
fun akoko, fun ojo, ati fun odun. Gen. 1:14.

1. mf Olorun wa, je k’iyin Re


Gb’ohun gbogbo wa kan;
Owo Re yi ojo wa po,
Odun miran si de.

2. Ebo wa ngoke sodo Re,


Baba, Olore wa:
Fun anu ododun ti nsan
Lati odo Re wa.

3. N’nu gbogbo ayida aye,


K’anu Re wa sibe:
B’ore Re si wa si ti po,
Beni k’iyin wa po.

4. N’nu gbogbo ayida aye,


A nri aniyan Re;
Jowo, je k’anu Re ‘kanna
Bukun odun titun.

5. B’ayo ba si wa, k’ayo na


Fa wa si odo Re;
B’iya ni, awa o korin
B’ibukun Re pelu.
Amin.
187
7.7.7.7.
Igba mi mbe li owo re. OD. 31:15.

1. mf Alakoso ti orun,
Alanu at’Ologbon;
Igba mi mbe l’ owo Re,
Opin gbogbo l’ase Re.

2. Ase Re l’o da aye


Ati ibi mi pelu,
Obi, ile, on igba
Nipa Re ni gbogbo won.

3. p Igb’ aisan on ilera,


Igba ise on oro,
Igba ‘danwo, ibinu,
Igba ‘segun, iranwo.

4. Igba iridi Esu,


Igba ‘to ‘fe Jesu wo,
Won o wa, won o si lo,
B’Ore wa orun ti fe.

5. ff Iwo Olore-ofe,
‘Wo ni mo f’emi mi fun,
Emi jewo ife Re,
Emi teriba fun O.
Amin.
188
7.7.7.7.D
E yipada kuro ninu ona buburu nyin; nitori kini eyin o se ku. Esek. 33:11.

1. mpElese, e yipada,
Ese ti e o fi ku?
Eleda yin ni mbere
To fe ki e ba On gbe;
Oran nla ni O mbi yin,
Ise owo Re ni yin;
cr A! eyin alailope
Ese t’e o ko ‘fe Re?

2. p Elese e yi pada,
Ese ti e o fi ku?
Olugbala ni mbere;
Eni t’O gb’emi yin la;
Iku Re y’o j’asan bi?
E o tun kan mo ‘gi bi?
di Eni ‘rapada ese
Te o gan or’ofe Re?

3. p Elese, e yi pada,
Ese ti e o fi ku?
Emi mimo ni mbere
Ti nf’ojo gbogbo ro yin;
E ki o ha gb’ore Re?
E o ko iye sibe?
di Ati nwa yin pe, ese
T’e mbi Olorun ninu?

4. cr Iyemeji ha nse yin


Pe ife ni Olorun
E ki o ha gboro Re?
K’e gba ileri Re gbo?
p W’Oluwa yin lodo yin,
pp Jesu sun, w’omije Re;
Eje Re pelu nke pe:
Ese ti e o fi ku?
Amin.
189
6.5.9.14.9. & Ref.
Nitori ti Oluwa mbo wa se idajo aye. OD. 96:13.

1. mf Ojo nla kan mbo wa,


Ojo nla kan mbo;
T’awon eniyan mimo at’elese y’o pinya,
Iwo ha setan fun ojo na?
cr O ha setan? O ha se tan?
O setan fun ojo idajo?
O ha setan? O ha setan?
Fun ojo ‘dajo.

2. f Ojo didan kan mbo


Ojo na mbo wa,
ff Ojo didan ‘kan mbo, nigbose,
Sugbon didan re je ti awon t’o fe Oluwa
Iwo ha se tan fun ojo na?

3. p Ojo ‘banuje mbo,


Ojo na mbo wa,
Ojo ‘banuje mbo nigbose
Ti elese y’o gbo pe: Lo, emi ko mo yin ri’
Iwo ha setan fun ojo na?
Amin
190
L.M.
Nitorina awon eniyan buburu ki yio dide duro ni idajo. OD. 1:5.

1. f Ojo ‘binu, ojo eru,


T’aye at’orun y’o fo lo,
di Kin’ igbekele elese?
p Y’o se le y’oju lojo na?

2. f Nigbati orun y’o kako


Bi awo ti a f’ina sun,
cr Ti ipe ajinde y’o ma dun
ff Kikan kikan, t’eru t’eru.

3. A! l’ojo na, ojo ‘binu,


T’ eda yio ji si ‘dajo,
cr Kristi jo se ‘gbekele wa,
di ‘Gbat’ aye, t’orun ba fo lo.
Amin.
191
L.M
Nitorina awon eniyan buburu ki yio dide duro ni idajo ,OD.15

1 f Ojo’binu,ojo eru,
T’aye at’ orun y’o fo lo,
di Kin’igbekele elese?
p Y’o se le y’oju l’ojo na?

2 f Nigbati orun y’o kako


Bi awo ti a f’ina sun,
cr Ti ipe ajinde y’o ma dun
ff Kikan kikan , t’eru t’eru

3 A ojo na, ojo ‘binu,


T’eda yio si’dajo,
cr Kristi jo se gbekele wa,
di ‘Gbat’ aye t’orun ba fo lo,
Amin
192
11.11.11.9.&Ref
Nitori ailabawon li ebun ati ipe Olorun.Rom 11:29

1. f Ipe t’o ni ‘bukun lat’oke orun,


Ipe t’o ni ‘bukun li emi npe wa,
O fi agbara fun eni ti nsare,
Eni t’o ba gbagbo, fun o ni.
ff Fun o ni, ara, fun o ni,
Gbekele ‘leri Re to daju (ara mi)
Fun o ni, ara, fun o ni,
Eni t’o ba gbagbo, fun o ni.

2 mp. O ti f’eje Re ‘yebiye se ‘laja,


Omo Olorun ti sise igbala
Gbogbo ise na ti pari, o pari
mf Lati gba ‘bukun na, fun o ni.

3. mp Y’o gba eni t’o ba gbagbo la d’opin,


Otito li eyi o da wa loju,
Gba ise otito ati ‘yanu yi,
f Eni t’o ba gbagbo, fun o ni.

4. mpMa siyemeji mo, wa ‘do Re loni,


mf Kuro ninu ese re patapata,
‘Tori anu Re nla, y’o dariji o,
Y’o si s’amona re de orun.

5. mpLohun ni ‘le ogo ao korin ‘yin Re,


mf Li ohun isegun; lae ati lae,
B’ipe na tile pe, sibe titun ni,
ff Ogo, Aleluya, fun o ni.
Amin.
193
7.6.8.6.7.6.11.&.Ref.
Pe Kristi Jesu wa si lati gba elese la I Tim 1:15

1 mf Mo ni Olugbala kan,
O wa lati orun,
p O ku fun mi ni Kalfari
Lati fi’fe Re han,
cr Iru ‘fe t’o ni simi
O nma ‘wo Re si O,
Wo ko ha ni gba Jesu ni nitire
mf Wo ko ha ni je ki O gba o,
Oun y’o je ore toto fun o,
Yio we okan re mo,yio si so di pipe
Wo ko ha ni gba Jesu mi ni tire?

2 f Mo l’Olugbala rere
O ngb’ohun ipe mi,
cr O nru gbogbo wahala mi,
O m’ese mi duro,
mf O s’oninure tobe,
O l’anu at’ oto
‘Wo ko ha ni gba Jesu mi nitire?

3 f Mo l’Olugbala toto,
On y’o ma ba mi gbe,
mf Yio si di owo mi mu,
Titi un o fi gunle ,
mp L’ojo kan n’nu ogo Re,
f Un o r’Olgbala mi,
Ara,’wo ko ha ni gba A l’Oluwa.
Amin
194
8.7.8.7 & Ref.
Ma lo, ma si tun d’ese mo. Jn. 8:11.

1 . mfO gbo ohun Jesu t’O nwi


cr Pe k’o fi ese sile,
O ti mu ‘gbala ofe wa
Bi iwo ba je tele,
f Wa, tele Olugbala re,
Fi ayo gba Olutunu;
Ohun Re npe o, asako,
Sa bere, ki o si gbagbo.

2. cr Ese t’o ko f’okan re fun


p Jesu t’O ku l’ori ‘gi?
cr O wipe, mo dariji o,
Gb’agbelebu, tele mi.

3. mpUn o wa s’odo Re, Jesu mi,


Un o fi aye mi fun O,
mf Un o feran Re, Un o sin O,
cr Gba mi loni, Oluwa.

4. mf Jesu gba mi la, O gba mi.


mpB’O ti leri lati se,
Gbogb’ eru ese li O ru,
f Wa, y’O si gba o pelu.
Amin.
195
6.6.6.5. & Ref.
E wa sodo mi gbogbo eyin ti nsise, Emi o si fi isimi fun yin. Mat. 11:28.

1. mf Wa gba isimi re,


Mase je ‘rora mo,
di Wa s’odo Jesu re,
Ma se jafara,
mp Adura, ng’oke lo,
Angel’ nteri won ba,
mf Aye dapo mo won,
Mase jafara.

2. p Okunkun l’aye yi
Lala inu re po,
f Wa s’agb’ Olugbala
mf Mase jafara.

3. mfGb’eru ese re wa,


Jesu ti ku fun o,
f On y’o t’ewo gba o,
Mase jafara.

4. cr Igba ko duro pe,


Wawa l’akoko nlo,
mf Idajo si mbo wa,
cr Mase jafara.

5. mf Wa, awa mbe o, wa;


f Wa, ye gb’oke gb’odo;
Wa mura fun ile,
Mase jafara.
Amin.
196
8.7.8.7. & Ref
Loni, bi eyin ba gbo ohun Re e mase se aya yin le. Heb. 4:7.

1. mf Wa, nigbati Kristi npe o


Wa, ma rin ‘na ese mo,
Wa, tu gbogb’ ohun t’o de o
Wa, bere ‘re ‘je t’orun.
f O npe o nisiyi,
Gbo b’Olugbala ti npe,
O npe o nisiyi,
Gbo b’Olugbala ti npe.

2. cr Wa, nigbati Kristi mbebe,


Wa, gbo ohun ife Re,
‘Wo o ko ohun ife Re,
Wo o si ma sako sa?

3. mf Wa, mase f’akoko d’ola,


Wa, ojo ‘gbala ni ‘yi,
Wa fi ara re fun Kristi,
Wa wo ‘le niwaju Re.
Amin.
197
10.10.10
A se bi O ti wi tan, aye si mbe sibe.
Lk. 14:22.

1. f “Aye si mbe!” ile Od’agutan,


Ewa ogo re npe o pe “Ma bo”
p Wole, wole, wole nisisiyi.

2. Ojo lo tan, orun si fere wo,


Okunkun de tan, ‘mole nkoja lo,
p Wole, wole, wole nisisiyi.

3. Ile iyawo na kun fun ase;


f Wole, wole to oko ‘yawo lo;
cr Wole, wole, wole nisisiyi.

4. f Onkun! o nkun! ile ayo na nkun


Yara! mase pe ko kun ju fun O!
p Wole, wole, wole nisisiyi.

5. f` “Aye si mbe” ilekun si sile,


Ilekun ife, iwo ko pe ju,
p Wole, wole, wole nisisiyi.

6 . f Wole, wole! tire ni ase na.


Wa gb’ebun ‘fe ayeraye lofe!
p Wole, wole, wole nisisiyi.

7. f Kiki ayo l’o wa nibe, wole!


Awon angeli npe o fun ade,
p Wole, wole, wole nisisiyi.

8. ff L’ohun rara n’ipe ife na ndun!


cr Wa ma jafara, wole, ase na!
p Wole, wole, wole nisisiyi.

9. p K’ile to su, ilekun na le ti


p ‘Gba na o k’abamo! “o se! ose!”
cr O se, ose, ko s’aye mo; o se!
Amin.
198
8.8.8.8.8.9.8.9.
Jesu ti Nasareti li o nkoja. Lk. 18:37.

1. f Eredi irokeke yi
Ti eniyan ti now koja?
‘Jojumo n’iwojopo na,
Eredi re, ti won nse be?
f Won dahun l’ohun jeje pe;)2ce
di “Jesu ti Nasareti l’O nkoja.”)2ce

2. mf Tani Jesu? Ese ti On


Fi nmi gbogbo ilu bayi?
Ajeji Ologbon ni bi?
Ti gbogb’eniyan nto leyin?
p Won dahun l’ohun jeje pe;)2ce
cr “Jesu ti Nasaret’ l’O nkoja”)2ce

3. Jesu on na l’O ti koja


p Ona irora wa l’aye
‘Bikibi t’On ba de, won nko
Orisi arun wa ‘do Re
f Afoju yo, b’o ti gbo pe;)2ce
cr “Jesu ti Nasaret’ l’O nkoja”)2ce

4. On si tun de! N’ibikibi


Ni awa si nri ‘pase Re,
On nrekoja l’ojude wa
O wole lati ba wa gbe,
f Ko ha ye k’a f’ayo ke pe)2ce
di “Jesu ti Nasaret’ l’O nkoja”)2ce

5. Ha! E wa, eyin t’orun wo!


f Gba ‘dariji at’itunu,
p Eyin ti e ti sako lo
cr Pada gba or’ofe Baba,
Eyin t’a danwo abo mbe)2ce
f “Jesu ti Nasaret’ l’O nkoja”)2ce

6. p Sugbon b’iwo ko ipe yi,


cr Ti o si gan ife nla Re;
On yio peyinda si o,
Yio si ko adura re;
p ‘O pe ju” n’igbe na y’o je)2ce
pp “Jesu ti Nasaret’ ti koja”)2ce
Amin.
199
6.4.6.4.
Loni bi enyin ba gbo ohun Re, e mase se aya nyin le. OD. 95:7-8.

1 . f Loni ni Jesu pe!


Asako wa,
p A! okan okunkun
Ma kiri mo.

2. f Loni ni Jesu pe!


Gbo ohun Re
Ki ‘gba Re to koja
Teriba fun.

3. f Loni ni Jesu pe!


Sa asala,
p Iji igbesan mbo,
cr Iparun mbo.

4. f Loni ni Jesu pe!


Jowo ‘ra re;
Ni ‘gba anu ma je
K’O binu lo.
Amin.
200
7.6.7.6
Eniti o ba si to Mi wa, Emi ki yio taa nu, bi o ti wu ki o ri. Jn. 6:37.

1. mf Wa sodo Mi, alaare,


Un o fun yin n’isimi,”
p A! ohun didun Jesu,
Ti o p’elese wa
cr O nso, ti Ore-ofe
Ati t’alafia,
Ti ayo ti ko l’opin,
T’ife ti ko le tan.

2 . mf “E wa, eyin omo Mi”


Un o fun yin n’imole,
p A! ohun ife Jesu,
cr Ti nle okunkun lo.
p Awa kun fun ‘banuje,
Ati s’ona wa nu;
f Imole y’o m’ayo wa,
Oro y’o m’orin wa.

3. mf “E wa, eyin ti ndaku,


Un o fun yin ni iye
p Ohun alafia Jesu
T’o f’opin s’ija wa,
mf Oju ota wa koro,
Ija si le pupo
cr Sugbon ‘Wo fun wa n’ipa
f A bori ota wa.

4. mfEnikeni t’o ba wa,


Emi ki o ta nu
p A! ohun suru Jesu
cr T’o le ‘yemeji lo,
mfNinu ife iyanu,
T’o pe awa elese,
B’a ti le je alaye
S’odo Re, Oluwa.
Amin.
201
7.7.7.7.
E teti lele, ki e wa sodo mi. Isa. 55:3.

1. Y’ara, elese, k’o gbon!


Ma duro d’ojo ola;
Ma kegan ogbon, n’tori
p Atunri re y’o soro.

2. Yara lati wa anu,


Ma reti ojo ola,
Akoko re lekoja
K’ise ale yi to tan.

3 . f Yara, elese pada,


Ma reti ojo ola;
mpKi fitila re to ku,
K’ise igbala to tan.

4. f Yara lati gba ‘bukun!


Ma duro o d’ojo ola;
Ki egbe ma ba ba o
Ki ile ola to mo.
Amin.
202
8.7.8.7.11.
Enikeni ti o ba si fe, sssski o gba omi iye na lofe. Ifi. 22:17.

1. mf Otosi elese, e wa,


‘Wa ni wakati anu,
Jesu setan lati gba yin,
O kun f’anu at’ife,
cr O si le, se O mura tan, ma foya.

2. mf Eyin alaini, e wa gba


Ogo Olorun l’ofe
Gbagbo toto, ronu toto
Or’ofe ti o nfa wa
cr Wa ‘do Jesu laini owo, sa wa ra.

3. mpMa je k’okan yin da yin ro,


Mase ro ti aye yin,
Gbogbo yiye t’O mbere ni
Ki e sa mo aini yin
cr Eyi to fun yin bi ‘mole lokan yin.

4. mpEyin t’eru npa, t’are mu


T’e sonu te si segbe
Bi e duro tit’e o sise
E ki yoo wa rara;
cr F’elese ni, On ko wa f’olododo.

5. mf Olorun goke l’awo wa;


O nfi eje Re bebe,
cr Gbe ara le patapata,
Ma gbekele ohun mi,
f Jesu nikan l’O le s’elese l’ore.

6. ff Angeli at’awon mimo


Nkorin ‘yin Od’agutan;
Gbohungbohun oruko Re
Si gba gbogbo orun kan,
Aleluya! Elese le gberin na.
Amin.
203
8.6.8.6.4.
Israeli, yipada si Oluwa Olorun Re. Hos. 14:1.

1. mpPada, asako s’ile re,


Baba re l’o npe o,
Mase alarinkiri mo,
N’n’ese at’osi re;
p Pada; pada.

2. mpPada, asako s’ile re,


Jesu l’O sa npe o,
cr Emi pelu Ijo si npe,
Yara, sa asala;
pp Pada, pada.

3. mp Pada, asako s’ile re,


cr Were ni, b’o ba pe,
mf Ko si ‘dariji n’iboji;
Ojo anu kuru;
pp Pada, pada.
Amin
204
L.M.
E wa nitori ohun gbogbo setan. Lk. 14:17.

1. f Elese, gba ‘hinrere gbo!


Wa si ase Oluwa mi,
Gbo, k’o si m’ojo ore re,
Ohun gbogbo setan, ma bo!

2 . f Baba mura tan lati gba


Awon ‘mo Re t’o pada wa;
Olugbala re mura tan,
O na ‘wo ogbe Re si O.

3. Emi ife Re mura tan


Lati m’okan lile kuro,
Lati f’eje na s’eleri,
K’a we o, k’a so o d’omo.

4. f Awon angeli mura tan,


Lati y’ayo ibukun re;
Won y’o fi duru korin ‘yin
Ore-ofe irapada.

5. f Baba, Omo, Emi Mimo


Mura pelu om’ogun Re
i Gbogbo orun y’o si ho pe,
Oku ye, a ri eni nu!
Amin.
205
7.7.7.D.
Oluwa-odo Re ni mo sa pamo si. O.D. 143:9

1. mp Emi are ti nsako


Kuro li arin ayo,
cr Wo Jesu t’a kan mo ‘gi,
Sa lo s’ibi ogbe Re;
Ri n’nu eje ‘wenumo,
cr Dide si iwa-mimo.

2. mf N’nu Kristi l’alafia wa


Alafia t’a ko le so;
‘Rora Re n’itura re
Iku Re ni iye re,
Dide nipa ‘rele Re,
Ohun gbogbo mbe n’nu Kristi.

3. mf Gba eri otito gbo,


Eyin t’a fi Jesu fun!
Eyin si le kun f’ayo,
K’e m’adun orun l’aye,
Ki igbe aye yin je
Ti ife t’o kun f’ogo.

4. f Eyi l’alafia na,


Ta pese fun gbogb’eda,
Ileri Olorun ni,
Ebun Re ran araye,
Gba ‘bukun yi ninu Krist
Nisiyi ati laelae
. Amin.
206
12.9.12.9.& Ref.
Nigbati o ba wo o, yio ye. Num. 21:8.

1. mpIye wa ni wiwo Eni t’a kan mo ‘gi,


Iye wa nisisiyi fun o;
Nje wo O elese k’o le ri ‘gbala
Wo Eni t’a kan mo ‘gi fun o
ff Wo! Wo! Wo, k’o ye,
f Iye wa ni wiwo, Eni t’a kan mo ‘gi
Iye wa nisisiyi fun o;

2. mpKini On se wa bi eleru ese


Ba ko ba gb’ebi re ru Jesu!
Eje ‘wenumo ha se ti iha Re san,
Bi ‘ku Re ko ba san gbese re?

3. p Ki’ s’ekun ‘piwada ati t’adura re,


pp Eje na lo s’etutu f’okan,
cr Gbe eru ese re lo si odo Eni
Ti o ti ta eje na sile.

4. mf Ma siyemeji s’ohun ti Olorun wi


Ko s’ohun to ku lati se mo
f Ati pe Oun yio wa nikeyin aye,
Y’o si s’ase pari ise Re.

5 ff Nje wa f’ayo gba iye ainipekin


mf Ni owo Jesu ti fi fun ni;
mp Si mo daju pe iwo ko le ku laelae
Gbati Jesu ododo re wa.
Amin.
207
11.11.11.7. & Ref.
Filipi so fun pe, “Wa wo O”. Jn. 1:46.

1. mf Ipe ihinrere na ni yi, Wa wo,


Fun gbogbo orile ede ni, Wa wo,
Jesu mu igbala ofe wa, Wa wo,
Ohun ti O se fun mi.
f Wa wo, wa wo,
Ohun ti O se fun mi.
cr O r’okan mi n’nu ese
O si we mi mo toto,
mf Eyi ni O se fun mi.

2. Oun ki yoo tan o je laelae, wa wo,


Y’o gba o ninu wahala re gbogbo
cr O nduro lati tewo gba o wa wo
Gbogb’ohun to se fun mi.

3. f Wa f’Olugbala se igbekele re,


Tete sa si abe abo re, wa wo
mp Ninu anu Re ni k’o ma gbe, wa wo
Ohun ti O se fun mi
. Amin.
208
11.9.11.9, & Ref.
Nigbati o ba wo o, Yio ye: Num. 21:8.

1. mf Oluwa ran mi ni ‘se, Aleluya!


Iwo ni un o je ise na fun;
A ko s’inu oro Re, Aleluya!
P’eni t’o ba wo Jesu y’o ye.
ff Wo, k’o ye, Arakunrin,
Wo Jesu ki o si ye,
mf A ko s’inu oro Re, Aleluya!
P’eni t’o ba wo Jesu y’o ye.

2. mf A ran mi n’ise ayo, Aleluya!


Un o j’ise na fun o ore mi;
cr Ise lat’oke wa ni; Aleluya!
mpJesu so, mo mo pe oto ni.

3. mf A n’owo iye si o, Aleluya!


f A o fi ‘ye ailopin fun o;
T’o ba wo Jesu nikan, Aleluya
ff Wo o, On nikan l’o le gbala.
Amin.
209
7.6.7.6.D.&Ref.
Eje Jesu Kristi Omo Re nin we wa nu kuro ninu ese gbogbo. I Jn. 1:7.

1. mf Isun ‘wenumo kan mbe


cr Lati oke Kalfari,
Oluwa si isun na
mf Fun gbogbo elese,
Nisiyi ohun re npe
Lati so d’ominira
f E wa fun iwenumo
cr Nibi ite-anu.
p Isun ti nsan ni Kalfari
Isun Kalfari na nsan
cr Lofe lo nsan, fun gbogbo wa ni
Isun Kalfari na nsan

2. mpBi eru ese npa o


Ti are si mu o,
Agbara mbe n’isun na,
Wa we n’nu isun na
mf Iwosan mbe ninu re
Pelu iwenumo,
Omi anu nsan titi
Lat’ oke Kalfari.

3. mf Orisun iye n’ise,


Lofe l’o nsan fun wa,
mpBere, we ki o si mo,
Si gba omnira re,
f Gba Kristi l’Oluwa re
Y’o so o di kanga
Alafia at’ayo
Y’o ma san ninu re.
Amin.
210
7.7.8.7.6.7.8.7.& Ref.
Nitori Olorun fe araye tobe ge, ti o fi omo bibi Re kansoso fun ni. Jn. 3:16.

1. mf Agogo ihinrere
Nlu lat’ilu de ilu,
‘Bukun ati ‘gbala ofe
Ni won fun o at’emi,
mpOlorun f’araye
T’o fi Omo Re fun wa;
f P’enikeni ti o gb’A gbo
Y’o ni ‘ye ainipekun.
f ‘Hinrere b’o ti ndun
Lati ilu de ilu,
‘Hinrere l’ofe ni,
‘Hinrere to n’ibukun.

2. mf Agogo ihinrere
Npe wa si ase nla na,
f Jo, ma ko ipe Ouwa,
Ma si ko ‘pe or’ofe,
mp Akara ‘ye l’Emi,
Je n’nu re okan ebi,
p B’ese re pon bi ododo
mf ‘Won y’o funfun bi owu.

3. Agogo na nma nkilo


B’o ti nlu lojojumo
Ni p’ohun to le de b’awon
To f’akoko jafara
f S’asala f’emi re,
Ma duro ni petele,
mf Mase b’oju wo eyin re,
Ki egbe ma se ba o.

4. f Ayo ni agogo na,


ff Fi nlu kakiri aye,
Nso nipa ti idariji
Ti Jesu y’o fi fun wa
‘Hinrere t’ayo nla
L’o mu wa fun gbogb’eniyan,
f Fun o l’a bi Olugbala
Krist’ Oluwa at’Oba.
Amin.
211
S.M. & Ref.
Eniti o ba to mi wa, Emi ki yio taanu bi o ti wu ki o ri. Jn. 6:37.

1. f Oluwa mo gb’ohun Re,


Ti npe mi wa ‘do Re,
Fun ‘wenumo n’nu eje Re
To san ni Kalfari.
mf Mo mbo Oluwa
Mo mbo sodo Re
cr We mi ninu eje Re
To nsan ni Kalfari.

2. mpBi mo mbo n’nu ailera,


‘Ranlowo Re daju,
‘Wo mu ailera mi kuro,
Emi si di mimo.

3. mf Jesu li O pe mi
Si ‘gbagbo on ife,
Si ‘reti ati eje Re
To nsan ni Kalfari.

4. p A! eje etutu
pp A! ore ‘rapada
cr A! ebun Kristi Oluwa wa
mf L’okun, ododo wa.
Amin.
212
L.M.
Nje gbogbo eniti ongbe ngbe, e wa si ibi omi. Isa. 55:1.

1. mf Gbogbo eni t’ongbe ngbe, wa!


f Olorun npe gbogb’ elese;
cr Ran anu on ‘gbala lofe;
Ran or’-ofe ihinrere.

2. mpWa s’ibi omi iye, wa!


Elese, je ‘pe Eleda,
Pada, asako, bo wa ‘le,
Ofe ni ore mi fun yin!

3 . mfWo apata ti nsun jade!


Isun ‘marale nsan fun o,
Eyin ti eru ese npa,
E wa, laimu owo lowo.

4. mfKo s’iparo t’e le mu wa,


cr E f’ini yin gbogbo seyin,
f F’igboya gb’ebun Olorun,
Ni idariji n’nu Jesu.
Amin.
213
7.7.7.7..D
E wa sodo mi gbogbo enyin ti nsise, ti a si dieru wuwo le lori. Mat. 11:28.

1. mf Wa, alare, elese,


cr Eyin t’eru ese npa;
f Jesu np’asako wa ‘le,
Wa ‘fiji l’od’Olorun!
di Eyin ti ese te ba,
Je ipe Olugbala
Wa uno fun yin ni ‘simi
Wa, un o gba gbogbo yin la.

2. mf Jesu t’o kun fun oto


cr Awa gba oro Re gbo,
Fi oto anu Re han,
Ko eru ese wa lo;
Awa fe gbokanle O,
K’a sa s’abe anu Re,
K’a r’isimi lodo Re.

3. p Ibanuje te wa ba,
pp Ese wa wo wa lorun,
Aigbagbo bo wa mole
Pelu ‘binu Olorun;
mf Wo! A to wa fun ‘rora,
‘Wo Oloto Olore,
Da emi are wa n’de,
Fi ‘dariji f’okan wa.
Amin.
214
9.9.9.6.D
E wa sodo mi gbogbo enyin ti nsise, ti a si di eru
wuwo le lori emi o si fi isimi fun nyin. Mat. 11:28.

1. mf Wa s’odo Jesu, mase duro;


L’oro Re l’o ti fona han wa,
O duro li arin wa loni,
O nwi pele pe, wa!
crIpade wa yio je ayo,
Gb’okan wa ba bo lowo ese,
T’a o si wa pelu Re, Jesu,
N’ile ayeraye!

2 . f Jek’omode wa! E gb’ohun Re;


Jek’okan gbogbo kun fun ayo,
K’a si yan Jesu l’ayanfe wa,
E ma duro, e wa.

3. mf Ranti p’O wa pelu wa loni,


F’ eti s’ofin Re, k’o si pamo;
cr Gbo b’ohun Re ti nwi pele pe
Eyin omo Mi wa.
Amin.
215
9.8.10.8.& Ref.
Bi enikeni ba nsin mi, ki o ma to mi lehin. Jn. 12:26.

1. f Tani y’o koko tele Jesu?


Tani y’o ko gb’agbelebu?
mf Enikan se tan, enikan nlora
f Tani y’o de ade na?
ff Tani y’o ko de ade na?
Tani y’o koko tele Jesu?
Tani y’o koko tele Jesu n’siyi?
Tele de opin?

2. mf Tani y’o koko tele Jesu?


Wa wole leba ese Re,
Tani y’o ko ko aniyan re wa?
cr Lese Baba n’ite-anu

3. mf Tani y’o koko tele Jesu?


Tani y’o ko ‘yin Oko Re?
cr Tani nfe ba won korin ‘rapada
f Orin Aleluya loke.
Amin.
216
12.11.12.11.& Ref.
E ba Olorun laja. II Kor. 5:20.

1. mp Gbo elese bi Olorun re ti npe o,


cr Ti O si nkilo pelu ohun anu;
Feti s’ohun Re ki ‘dajo ma ba o,
mf “Ikore nkoja lo, erun y’o pari”
“Ikore nkoja lo, erun y’o pari,”
“Ikore nkoja lo, erun y’o pari,”

2. mf Oluwa nke pe k’o kuro l’ona ‘parun,


Ipe anu Re ni eyi je fun o;
Yara n’siyi, bo s’abe abo ife Re,
“Ikore nkoja lo, erun y’o pari,”

3. cr K’ibanuje at’eru ma ba je ‘pin re,


Mase ko ipe anu to nko si o,
mf Mura, elese, gbon, k’o si gba ipe na,
“Ikore nkoja lo, erun y’o pari,”

4. Laipe, Jehofa y’o wa nin’agbara re


Lati fenikokan b’ise re ti ri:
Ara, mura f’ojo na, iku ko dojo
“Ikore nkoja lo, erun y’o pari,”

5. mpOluwa y’o pe o siwaju ‘te dajo;


Nitorina f’Olugbala s’ore re,
cr Omo fi okan re fun, k’o si juba Re
“Kore Re nkoja lo, erun y’o pari,”
Amin
217
7.10.7.7.&Ref.
Nitori ailabawon li ebun ati ipe Olorun. Rom. 11:29.

1. mf ‘Gbala-ofe s’owon bi,


F’eni t’o ba fe, f’eni t’o ba fe?
Tal’ o nfe ayeraye?
Eni t’o ba fe le wa.
mp Eni t’o ba fe le wa (‘do Jesu)
Eni t’o ba fe le wa (‘do Jesu)
f ‘Gbala-ofe wa f’enikeni
Eni t’o ba fe le wa (le wa)

2. f Olorun fe gbogbo wa,


Eni t’o ba fe, eni t’o ba fe
Bi a ba gba ipe Re
Eni t’o ba fe le wa.

3. f Sibesibe O npe wa,


Eni t’o ba fe, eni t’o ba fe
Ife mimo Re npe wa,
Eni t’o ba fe le wa.
` Amin.
218
8.7.8.7.4.7.
Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Israeli, e wa mi, enyin o si ye. Amo. 5:4.

1. mf Elese o ha gan ise


T’a f’anu an lat’oke;
Ohun jeje l’o fi ranse
Oro Re kun fun ife;
Te ti lele,
Ise Re kun fun ife.

2. f Gbo awon ojise rere,


Won nj’ise Oba Sion;
“Idariji fun elese
L’ofe l’oruko Jesu”
cr Bo ti po to
p ‘Dariji l’oruko Re.

3. f F’okan itanje at’eru


Won mu ‘bale aya wa,
Won wa fi ise itunu,
Le omije yin kuro;
p Ojise ‘re,
pp Nu omije nu kuro.

4. mf Tani ti gba ihin wa gbo?


Tani gb’oro ayo na?
T’o gba ihin ‘dariji mu
Ti Oluwa na si yin?
E ha le gan
Ore anu Oluwa.
Amin.
219
L.M.
Bi eyin o ba gbo ohun re, e ma se aya nyin le. OD. 95:7,8.

1. f Mura, elese, lati gbon,


Ma duro de ojo ola;
Niwon b’o ti kegan ogbon,
Be l’o si soro lati ri.

2. mfMura lati bere anu,


Ma duro de ojo ola;
Ki igba re o ma ba tan,
p Ki ojo ale yi to tan.

3 . f Mura, elese, k’o pada,


Ma duro de ojo ola;
p Nitori k’ egun ma ba o,
K’ ojo ola k’o to bere.

4. f Mura lati gba ibukun,


Ma duro de ojo ola;
p Ki fitila re ma ba ku,
K’ise rere re to bere.

5. f Oluwa, y’elese pada,


Ji kuro ninu were re;
Ma je k’o tapa s’imo Re,
p K’o ma f’egbe re se ‘lora.
Amin
220
C.M.
Eje Jesu Kristi Omo re ni new wa nu kuro ninu ese wa gbogbo. I Jn. 1:7.

1. mf Nihinyi n’isimi gbe wa,


Niha re t’eje nsan;
Eyi nikan n’ireti mi,
p Pe Jesu ku fun mi.

2. Olugbala, Olorun mi,


Orisun f’ese mi;
Ma f’eje Re won mi titi,
K’emi le di mimo.

3. mpWe mi, si se mi ni Tire,


We mi, si je temi;
We mi, k’is’ese mi nkan,
Owo at’okan mi.

4. f Ma sise l’okan mi, Jesu,


Titi ‘gbagbo y’o pin;
Tit’ ireti y’o fi dopin,
T’okan mi y’o simi.
Amin.
221
7.7.7.7.
E wa Oluwa nigbati e le ri I, e pe e nigbati o wa nitosi. Isa. 55:6.

1. f Ojo nsure, o nkoja;


p Iku nsure, o de tan;
cr Elese nsawada ni!
p Ojo at’iku now o.

2. Emi nsure, t’o ba pin,


cr ‘Wo ko le pada mo lae;
‘Wo o bo s’ainipekun;
Ko ha ye k’iwo ronu?

3. f Olorun ngbo, gbadura,


Ki igba re to koja;
K’Ite ‘dajo Re to de,
K’ anu to tan k’esan de.

4. mf Mura giri, iku mbo,


B’o ba duro, o segbe;
di Ma sun mo, dide, sare;
Olugbala nreti re.
Amin.
222
S.M.
E jeki a se lala lati wo inu isimi na. Heb. 4:11.

1. mf Nibo n’isimi wa
‘Simi f’okan are?
Lasan l’a wa s’opin okun,
Ati s’opin ile.

2. Aye ko le fun ni
N’isimi ti a nfe;
K’a le pe titi laye ko!
p K’a si tete ku ko!

3. Aye kan mbe loke


T’o jinna s’aye yi,
Won ko nsiro odun nibe;
Ife ni aye na.

4. p Iku mbe, apa re


Kawo emi wa yi;
pp B’irora kikoro ti to
cr Ninu iku keji!

5. f Olorun jo ko wa
p K’a sa fun iku yi;
K’a ma ba le wa lodo Re,
K’a si segbe laelae.

6. Nihin l’ebe wa mo!


Aye ife pipe,
Ati isimi ailopin
Wa ninu Re nikan.
Amin.
223
7.7.7.7.D.
Nitori kini enyin o se ku, ile Israeli? Esek. 18:31.

1. mf Kini Jesu ‘ba tun se


Ju b’O ti ku fun o lo?
O ta je Re sile
Fun ‘repo ‘wo Olorun
di Ese t’iwo nse Jesu?
Ese ti o fe segbe?
Ife Re t’O nfi fa o,
Asan l’o je fun o bi?

2. p Elese, e yipada,
cr Olorun ti pinnu pe,
On y’o so yin di aye,
On y’o gba gbogbo eniyan
B’iku yin je ife Re
O ha le pe pe yin s’iye?
di F’eti s’ohun Re t’o ni
p Ese ti e fi segbe?

3. p Elese, e yipada,
cr Olorun mbe nitosi,
Olugbala re duro,
O na ‘wo alafia
mp Eyin ko ni to Mi wa!
Emi t’o nfi ‘ye fun ‘ni!
Mase ro pe nko n’ife,
p Ese ti e fi segbe!

4. mf Iwo y’o siyemeji


Si ife Olorun re?
‘Wo ki ha ni ‘gbagbo
S’ileri at’oro Re?
Wo Jesu t’o jiya re!
Ni ‘gbagbo si iya Re
di Gb’ohun eje Re nke pe,
p Ese ti e fi segbe!
Amin.
224
S.M.
E ma gba ara nyin niyanju lojojumo nigbati a npe loni. Heb. 3:13.

1. mf Tire l’ola Baba,


O wa n’ikawo Re;
B’oum’ola si mo ba ni,
Nipa ase Re ni.

2. Akoko yi nfo lo,


O ngbe emi wa lo,
Oluwa, mu ‘ranse Re gbon,
Ki won le wa fun O.

3. mpAkoko to nlo yi,


L’ayeraye ro mo;
Fi agbara Re Oluwa,
Ji agba at’ewe.

4. On kan l’aba ma du;


T’aba ma lepa re;
Pe k’igba ‘bewo wa ma lo,
Lai tun pada mo.

5. Je ka sa to Jesu
K’a si sure tete;
K’emi wa ma ba ku k’o ri
S’okun biribiri.
Amin.
225
C.M.
Gbogbo eniti ongbe ngbe, e wa sibi omi. Isa. 55:1.

1. Eyin t’ongbe ngbe, e wa mu


Omi iye ti nsan;
Lati orisun ti Jesu
Laisanwo l’awa nbu.

2. p Wo! b’o ti pe to t’e ti nmu


Ninu kanga eke
T’e nl’agbara at’ogun yin.
cr Ninu nkan t’o nsegbe.

3. Jesu wipe, isura Mi,


Ko lopin titi lae
Yio f’ilera laelae fun
Awon t’o gbo Tire.
Amin.
226
S.M.
Emi ati iyawo wipe, Ma bowa. Ifi. 22:17.

1. mp Emi okan wa npe,


O np’elese k’o wa;
‘Yawo, Ijo Kristi si npe
K’awon omo re wa.

2. f Je k’eni t’o gbo wi


F’awon t’o yika wa;
Eni t’ongbe ododo ngbe
K’o wa sodo Kristi.

3. Loto; eno t’o fe,


Je ki o wa l’ofe,
K’o mu omi iye l’ofe
Jesu l’o pe k’o wa.

4. f Gbo, bi Jesu ti npe,


ff Wipe, mo mbo kankan
Beni Jesu mo nreti Re,
Ma bo Olugbala
. Amin.
227
L.M. & Ref
E o si mo otito, otito yio si so nyin di ominira. Jn. 8:32.

1. Bi Krist’ ti da okan mi nde,


Aye mi ti dabi orun,
Larin ‘banuje at’aro
Ayo ni lati mo Jesu,
Aleluya! ayo l’o je
Pe, mo ti ri ‘dariji gba,
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s’ewu, Jesu wa nibe.

2 . Moti ro pe orun jina


Sugbon nigbati Jesu de
L’orun ti de ‘nu okan mi,
Nibe ni y’o si wa titi.

3 . Nibo l’a ko le gbe l’aye


L’o r’oke tabi petele,
L’ahere tabi agbala,
Ko s’ewu, Jesu wa nibe.
Amin.
228
9.8.9.7.& Ref.
Nitori omo mi yi ti ku, o si tun ye; O ti nu, a si ri i. Lk. 15:24.

1. Lekan, mo j’elese, sugbon mo


Ti gba ‘dariji l’od’Oluwa,
Lofe l’a fifun mi, mo si ri
Pe O npa oro Re mo.
Oko titun t’a ko sile n’n’ogo
T’emi ni toto, t’emi
Awon angeli mimo nko ‘rin na
Elese kan wa le
Tor’oko titun kan ti a ko n’n’ogo
T’emi ni toto, t’emi,
Leyin ‘dariji ese, oeun ni mo nlo
Nko tun sako mo.

2. Mo fi ‘rele kunle l’ese Krist’


Mo si mberu ‘binu Olorun,
Nigbat’ a si orun, ti mo ri
P’a ko ‘ruko mi sile;

3. Or’-ofe nikan l’o gba mi la,


Ayo ki l’o de si okan mi
A ti dariji mi mo si mo
P’eje Krist’ mu mi pe.
Amin.
229
12.12.12.12.& Ref.
Nigbati awa je elese, Kristi ku fun wa. Rom. 5:8.

1. L’ekan, oju mi ti fo s’ogo Oluwa


L’ekan, eti mi ti di s’ohun oro Re
L’ekan, mo te ade egun mo li ori,
Sugbon O ti dariji mi, ko tun si nkan mo.
Ko si nkan mo, beni, ko si nkan mo
O ti gbo adura mi, ko si nkan
Ko si nkan mo, beni, ko si nkan mo
O ti bo gbogb’ese mi, ko tun si nkan mo.

2. L’ekan ri, mo fe aye ati ogo re


Adun aye yi ti de mi ni igbekun
Sugbon On de n’jo kan l’ona ti nko le so
O fi eje Re bo ese mi, ko si nkan mo

3. Ohun rere ni lati wa l’odo Jesu


‘Gbati ‘danwo de, ti oju mi si sokun,
Ki nsa ri owo ife Re li ori mi
Ki nsi gbo ohun jeje Re wipe: ko si nkan
. Amin.
230
9.7.9.7.& Ref.
A dari ese re ti o po ji o. Lk. 7:47.

1. mf Bi a ba ko ese mi sile,
Ki nsi ri b’o ti po to,
Ibanuje mi yo ti po to,
Sugbon Baba ti we mi,
cr O f’eje Re ‘yebiye we mi mo
p O ko ese mi lo,
cr Nisisiyi mo di t’Oluwa laelae
On na si je temi.

2. mf Bi mo ba le wo yika kiri
Lati wa ese mi ri,
Nko le ri okan soso n’nu re
Mo ti gba idariji.

3. f Baba ko ranti ese mi mo,


Won ti lo s’okun ‘gbagbe
Un o korin iyin s’orukop Re
O sa ti dariji mi.
Amin.
231
9.9.9.9.8. & Ref.
Awa ti fi gbogbo re sile, awa si nto O lehin. Mat. 19:27.

1. mf Gbogb’ ohun t’o nfa mi, mo fi ‘le,


Nihin ni Kenan’ mo ri ayo;
f Alafia, ‘bukun ‘yebiye,
cr ‘Tori mo ngbe Kenani n’siyi.
f Mo ngbe Kenani nisisiyi,
Ni b’owara ibukun gbe wa,
Nibi a ni opo oro or’ofe,
Mo ngbe Kenani nisisiyi.

2 . f Mo ngbe lail’ewu nko je beru,


Olubgala mi wa nitosi,
‘Gba mo ba pe, y’o gbadura mi
‘Tori mo ngbe Kenani n’siyi.

3. mf Mo mu omi kanga alaigbe,


Ni Kenani ibugbe ife mi!
f Emi o so fun elomiran
cr Pe emi ngbe n’ile Kenani

4. ff Iyi ailopin ni mo mu wa
Fun Jesu, Oba Irapada;
mf Em’ o korin opo anu Re,
‘Tori mo ngbe Kenani n’siyi.
Amin.
232
7.7.7.
Jeki nwon wipe, da awon eniyan re si, Oluwa, ma si se fi ini re fun egan. Joe. 2:17.

1. p Jesu, l’ojo anu yi,


Ki akoko to koja,
A wole ni ekun wa.

2. p Oluwa m’ekun gbon wa,


Fi eru kun aya wa,
Ki oro iku to de.

3. Tu emi Re s’okan wa,


L’enu-ona Re l’anke
K’ilekun anu to se.

4. pp‘Tori ‘waya ija Re,


‘Tori ogun-eje Re,
‘Tori iku Re fun wa.

5. p ‘Tor’ekun kikoro Re,


Lori Jerusalemu,
Ma je k’agan ife Re.

6. Iwo onidajo wa,


‘Gbati oju wa ba ri O,
Fun wa n’ipo l’odo Re.

7. mf Ife Re l’a simi le,


N’ile wa l’oke l’ao mo
B’ife na ti tobi to.
Amin
233
C.M.
Nitorina e jeki a wa si ibi ite ore-ofe pelu igboya. Heb. 4:16.

1. mf Okan mi, sunmo ‘te anu,


N’ibi Jesu ngb’ebe
F’irele wole lese Re
A ko segbe n’be.

2. mpIleri Re ni ebe mi,


Eyi ni mo mu wa,
Iwo npe okan t’eru npa
Bi emi Oluwa.

3. p Eru ese wo mi l’orun,


Esu nse mi n’ise:
Ogun l’ode eru ninu
Mo wa isimi mi.

4. mfSe apata at’asa mi,


Ki nfi o se abo:
Ki nd’oju ti olufisun,
Ki nso pe, “Kristi ku”.

5. mf Ife iyanu! iwo ku,


cr Iwo ru itiju,
cr Ki elese b’iru emi
Le be l’oruko Re
. Amin
234
7.7.7.7
Olorun san fun mi emi elese. Lk. 18:13.

1. mpElese: mo nfe ‘bukun,


Onde: mo nfe ominira,
Alare: mo nfe ‘simi,
p “Olorun, sanu fun mi”.

2. mpIre kan, emi ko ni,


Ese sa l’o yi mi ka,
Eyi nikan l’ebe mi,
“Olorun , sanu fun mi”.

3. mpIrobinuje okan!
Nko gbodo gb’oju s’oke,
Iwo sa mo edun mi;
p “Olorun, sanu fun mi”.

4. cr Okan ese mi yi nfe,


Sa wa simi laya Re,
Lat’oni, mo di ti Re,
p “Olorun, sanu fun mi”.

5. mf Enikan mbe lor’ite,


Ninu Re nikan soso,
f N’ireti at’ebe mi,
p “Olorun, sanu fun mi”.

6. mf On o gba oran mi ro,


On ni alagbawi mi,
Nitori tire nikan,
p “Olorun, sanu fun mi”
Amin
235
S.M.
Bojuwo mi, ki O si sanu fun mi. OD. 119:132.

1. p Jesu, jo ranti mi
Ko si w’ese mi nu
cr Gba mi low’ese ‘binibi,
Si we okan mi mo.

2. p Jesu, jo ranti mi,


Mo kun fun aniyan,
cr Ki n’ je ‘ranse t’o n ife Re
Ki njogun ‘simi Re.

3. mfJesu, jo ranti mi,


L’arin ‘gbona ogun
N’nu ‘rora on banuje mi,
cr Je ‘lera, Iye mi.

4. p Jesu, jo ranti mi,


Ma je ki nsako lo,
cr N’nu ‘damu on okun aye
F’ ona orun han mi.

5. mfJesu, jo ranti mi,


cr Gba t’ iji ru s’oke
f ‘Gbati ota wa nitosi,
Jesu, jo sun mo mi.

6. Jesu, jo ranti mi,


‘Gba gbogbo re koja.
Ki nle r’ogo ainipekun,
Ki nsi le ba O yo.
Amin.
236
C.M.
Olorun sanu fun mi, emi elese. Lk. 18:13.

1. mpOluwa, ma m’oju kuro


L’odo mi t’o nyi ‘le,
Ti nsokun ese aye mi,
Niwaju ite Re.

2. mpIlekun kan si f’elese,


Ti nsoku ese won,
Mase se ‘lekun na mo mi,
Gba mi s’ile, Baba.

3. mpIwo mo, ki nto jewo re;


Ise mi l’aye mi,
At’iwa mi nisisiyi,
Gbogbo re ni ‘Wo mo.

4. mf Oluwa, mo de ‘bi ‘te Re,


Nibiti anu po!
Mo fe ‘dariji ese mi,
K’o mu okan mi da.

5. pp Oluwa ko ye k’emi so
Ohun ti mba bere,
O ti mo k’emi t’o bere
Ohun ti emi fe.

6. Oluwa mo toro anu


Eyiyi l’opin na;
Oluwa, anu l’o ye mi
Je ki nr’anu Re gba
. Amin.
237
8.8.8.D.
Sa wo o, awa to O wa nitori Iwo li Oluwa Olorun wa. Jer. 3:22.

1. mpO su mi lati ma sako,


O to ge, uno wa Olorun;
Mo teriba fun opa Re,
Fun O, mo ns’ofo n’nu ‘reti,
cr Mo n’Alagbawi kan l’oke,
Ore niwaju ‘te ife.

2. mf A! Jesut’o kun f’or’-ofe


Ju bi mo ti kun fun ese,
Lekan si mo tun now ‘ju Re
N’apa Re si gba mi mo ‘ra
L’ofe wo faseyin mi san;
Fe em’alaigbagbo sibe.

3. mp‘Wo m’ona lati pe mi bo,


Lati gb’eni t’o subu ro;
A! tor’anu at’oto Re
Dariji, ma je ki n ‘se o,
cr Tun ibaje okan mi se,
Ko si se n’ile adura.

4. mpA! fun mi ni okan riro


Ti y’o ma wa riri f’ese,
Fun mi ni iberu f’ese
Mu ko ta gbongbo ninu mi;
cr Ki nle beru agbara Re,
Ki nma tun d’ese si O mo
. Amin.
238
6.4.6.4.6.6.6.4
Nitori oruko Re, dari ese mi ji. OD. 25:11.

1. Ki ‘se l’aini ‘reti


Ni mo to ‘wa
Ki ‘se laini ‘gbagbo
Ni mo kunle,
Ese ti g’ori mi
Eyi sa l’ebe mi,
cr Eyi sa l’ebe mi,
Jesu ti ku.
2. p A! ese mi po ju,
O pon koko
Ada le, ada le
Ni mo nd’ese;
Ese aiferan Re
Ese aigba O gbo,
Ese aigba O gbo,
Ese nlanla.

3. mpOluwa, mo jewo
Ese nla mi,
O mo bi mo ti ri,
Bi mo ti wa;
p Jo, we ese mi nu,
K’okan mi mo loni,
K’okan mi mo loni,
Ki ndi mimo.

4. mf Olododo ni O,
O ndariji
L’ese agbelebu
Ni mo wole;
p Je k’ eje iwenu
Eje od’agutan,
Eje od’agutan,
We okan mi.

5. cr ‘Gbana alafia
Y’o d’okan mi,
‘Gbana un o ba O rin,
Ore airi;
mf Em’ o f’ara ti O;
Jo ma to mi s’ona,
Jo ma to mi s’ona,
Titi aye.
Amin.
239
8. 8. 8. 6.
Enikeni ti o to mi wa, Emi ki yio tanu bi o ti wu kori JJohn 6:37

1 mpBi mo ti ri , lai s’awawi,


Sugbon nitori eje Re
B’o si ti pe mi ki nwa
p Olugbala, mo de.

2. Bi mo ti ri, laiduro pe,


Mo fe k’okan mi mo toto,
S’odo Re to le we mi mo,
p Olugbala, mo de.

3. Bi mo ti ri, b’o tile je


Ija lode, ija ninu
Eru l’ode eru ninu,
p Olugbala, mode.

4. di Bi mo ti ri, o si are:
Mo si nwa imularada,
cr Iwo lo le s’awotan mi,
p Olugbala, mo de.

5. Bi mo ti ri, ‘wo o gba mi,


‘Wo o gba mi, t’owo t’ese
mf ‘Tori mo gba ‘leri re gbo,
p Olugbala, mo de.

6. mf Bi mo ti ri, ife tire,


L’o sete mi patapata,
Mo di tire, tire nikan:
p Olugbala, mo de.

7. cr Bi mo ti ri, n’nu ‘fe nla ni


T’o fi tito bi Re han mi:
Nihin yi ati ni oke:
p Olugbala, mo de.
Amin
240
7.7.7.7.
E mase je ki okan nyin daru. Jn. 14:1.

1. mp Ibu ife, o le je
Pe a p’anu mo fun mi,
Olorun mi ha le da
Binu ro fun elese?

2. di Mo ti mba n’nu je ti pe!


Mo ti nbi ninu ti pe!
Mo di ‘ti si ife Re,
Mo f’op’ese bi ninu.

3. mpA se ‘fe mi po to yi?


Bi Alagbawi mi wo;
Wadi re lodo Jesu,
Niwaju ‘te or’-ofe.

4 Nibe l’O f’ogbe owo


p Ati t’ese Re han mi,
Ife l’Olorun, mo mo,
cr Jesu ye, O si fe mi.

5. Jesu f’ife Re dahun


N’tori ife n’iwa Re,
Mo wole li ese Re,
‘Wo k’yo ha dariji mi?

6. Fi oju anu wo mi,


Si pe okan mi wa ‘le
S’okan lile di riro,
K’oju Re tu mi ninu
. Amin.
241
7. 6. 7. 6. D. 8c Ref
Gbo adura mi Oluwa, ki o sije ki igbe mi ki o wa sodo Re. Ps. 102:1

1. mf Olugbala, gb’ohun mi,


Gb’ohun mi, gb’ohun mi,
Mo wa s’odo re gba mi,
p Nibi agbelebu
di Emi se, sugbon o ku
Iwo ku, iwo ku,
Fi anu Re pa mi mo,
Nibi agbelebu
f Oluwa, jo gba mi,
Nki y’o bi o ninu mo
Alabukun, gba mi
Nibi agbelebu.

2. Ese mi po lapoju
Un o bebe, un o bebe
Iwo li ona iye
Nibi agbelebu,
Ore-ofe Re t’agba
L’ofe ni, L’ofe ni,
F’oju anu re wo mi,
Nibi agbelebu.

3. f F’’eje mimo Re we mi,


Fi we mi! fi we mi!
Ri mi sinu ibu Re,
p Nibi agbelebu.
‘Gbagbo l’o le fun wa ni
‘Dariji ‘dariji
Mo f’igbagbo ro mo o
Nibi agbelebu.
Amin
242
10.7.10.7. & Ref.
Fa mi, awa yo sare to O. O. Sol. 1:4.

1. mpOluwa, emi sa ti gb’ohun Re


O nso ife Re simi,
Sugbon mo fe nde l’ apa igbagbo
Ki nle tubo sun mo O,
mf Fa mi mora, mora, Oluwa
Sib’ agbelebu t’O ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Si b’eje Re t’o n’iye.

2. f Ya mi si mimo fun ise Tire,


Nipa ore-ofe Re,
Je ki nfi okan igbagbo w’ oke
K’ ife mi si je Tire,

3. f A! ayo mimo ti wakati kan


Ti mo lo nib’ ite Re;
‘Gba mo ngb’ adura si O, Olorun
Ti a soro bi ore.

4. f Ijinle ife mbe ti nko le mo


Titi un o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Titi un o fi de ‘simi.
Amin.
243
Lati wasu idasile fun awon igbekun. Lk. 4:18.

1. mf Lati ‘nu ide ibanuje


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa gba ominira at’ayo,
Jesu mo wa ‘do Re.
Alaisan, emi nfe iwosan;
Alaini, so mi di oloro;
cr Elese, mo wa si odo Re;
Jesu, mo wa ‘do Re.

2. Ninu ‘tiju ati ofo mi


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa jere nla n’nu iku Re,
Jesu mo wa ‘do Re.
‘Wo ni itunu fun ‘banuje;
‘Wo n’isimi fun gbogbo iji,
Orin dipo idanwo gbogbo,
Jesu mo wa ‘do Re.

3. cr Ninu rudurudu aye yi,


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa s’abe ase anu Re,
Jesu mo wa ‘do Re,
Mu mi kuro n’nu ife ara,
Kuro ninu aye asan yi,
Ki nle wa fi iye fo g’oke,
Jesu mo wa ‘do Re.

4. cr N’nu eru iku at’iboji


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa s’inu ayo ile mi,
Jesu mo wa ‘do Re,
Lati’nu iho iparun nla
Sinu alafia t’o jinle
Lati wa w’oju Re; ologo,
Jesu mo wa ‘do Re.
Amin
244
S.M.
Lehin igbati o ti ru ebo kan fun esem titi lae, o joko li owo otun Olorun. Heb. 10:12.

1. mf Gbogbo eje eran


T’a pa ni pepe Ju
cr Ko le f’okan l’alafia,
Ko le we eri nu.

2. cr Kristi O’dagutan
Ko gbogb’ese wa lo;
Ebo t’o ni iye lori
Ju eje eran lo.

3. f Mo fe fi igbagbo
Gb’owo le O lori,
Ki nsi f’ironupiwada
Se ‘jewo ese mi.

4. p Mo fi oju okan
Pe, egun ti kuro
A sope fun Od’agutan,
Agbekele ‘fe Re.
Amin.
245
C.M.
E yipada kuro ninu ona buburu nyin, nitori kinienyin o e ku. Esek. 33:11.

1. mf Wa, Oluwa Olusegun,


Fi ipa Re han wa:
Si fi agbara oro Re
Fo okan lile wa.

2. cr Gbogbo wa ‘ba t’oni bere


Si kanu ‘sise wa,
K’a peyinda si ese wa,
K’a wa Olugbala!

3. mp Jek’a mo O k’a mo ‘ra wa


Lojo anu wa yi;
Yi wa pada k’a ba le ye,
Si ko ese wa lo.

4. cr Fi opin si aigbagbo wa
K’O si da wa n’ide;
Je k’a kedun fun ese wa,
K’a le r’alafia.

5. mp Re wa sile, tun gbe wa ro


Si bukun otosi;
Je k’a mo riri arun wa,
Ati iwosan re.

6. Jek’a mo ebi ese wa,


Si m’ebi na kuro;
We okan ti ese ndamu
N’nu eje etutu.

7. F’ipo ewu t’a wa han wa,


Si f’ese wa ji wa;
Se wa pe ni iwa-mimo,
Si mu wa lo s’orun.
Amin.
246
L.M.
E wa sodo mi gbogbo enyin ti nsise, emi o si fi isimi fun yin.Mat. 11:28.

1. cr Jesu ‘Wo ore elese,


Mo wa ‘ranwo wa sodo Re,
Aye ati ese su mi,
Na apa Re k’O si gba mi!

2. mf Fi anu wo okan mi san;


‘Wo l’o le se awotan mi;
di Mo ti subu, mo si segbe,
K’aworan Re to tan n’nu mi.

3. Pese ‘bugbe na fun ‘ra Re,


Fi ife wonu okan mi;
Bayi ni mo le di mimo,
Ti ese ki o ba mi gbe.

4. Mo jewo pe agbara mi
Ko le mu mi ye ni Tire;
cr Jesu, ise na Tire ni,
Mo jewo gbogbo re fun O.

5. mf Kini uno fi ro ore Re?


Ese ni mi, ife ni O;
p Eyi nikan l’ebe mi pe –
pp Mo segbe, sugbon, ‘Wo ti ku!
Amin.
247
7.7.7.7.7.7.
Olorun sanu fun mi, emi elese. Lk. 18:13.

1. mf Olugbala Israel,
Wo mi lat’ori ‘te Re;
F’ikanu oto fun mi
cr Mu okan lile mi ro;
So okuta di eran;
Wo mi, si fo okan mi!

2. cr Baba nipa Ei Re
Fi gbogbo ese mi han,
Ki nmo ese ti mo da
S’imole at’ife Re;
Ese t’o kan Jesu mi,
T’o ta eje Re sile.

3. di Jesu, wa agutan Re,


Mu mi pada to O wa,
p Jeki now O ki nsokun
Kikoro bi Peteru,
mf Ki nle wi nip’or’ofe,
Iwo mo pemo fe O!

4. Ki nwa si iwaju Re,


B’agbowode ni ti se,
Ki nduro li okere,
Ki nlu okan-aya mi;
p Elese ko l’ebe ju –
Olorun, sanu fun mi.

5. cr Jo ranti mi fun rere,


L’afonifoji aye;
F’eje etutu han mi,
‘Gbat’are mu okan mi,
Jeki nfi itara ri
Jesu ti a pa fun mi!
Amin.
248
S.M.
Nitori ife Kristi nro wa. II Kor. 5:14.

1 . A! nibo ni mba lo,


Pelu ese nla mi
Tani mba f’iponju mi han
Ti mba ro ‘jo mi fun?

2. Olugbala npe mi;


Ese ti mo duro?
O npe elese t’are mu,
Sibe mo faseyin.

3 . Ki l’o fa mi seyin
Ti nko le fi sile
Ti ki o jek’Olugbala
Gba gbogbo okan mi

4 . Ohun egun aimo


T’o sa lumo ninu
Orisa ti nko fe jewo
Ese ‘koko n’nu mi.

5. Jesu, fi ‘denu na
Ti nko fe ri, han mi;
Jeki nle wadi ohun na
Ti nle mi lodo Re.

6. Oluwadi okan
F’ipa Re han n’nu mi;
Tan ‘mole si okunkun mi,
K’o si ‘boju kuro.

7 . Mo gbagbo wayi pe
Anu mbe ninu Re;
Oluwa, jek’o ri fun mi
Gege b’igbagbo mi!

8. Iwo nfe mu ‘dena


Ti mbe n’nu mi kuro;
Mu kuro, uno si jewo pe
Kiki ‘fe l’Olorun.
Amin.
249
8.8.8.D.
Oluwa, sanu fun mi, nitori ailera mi. O.D. 6:2.

1. cr Olorun mi, Olorun mi!


O to ge, nki o sako mo;
Nko ra eje Re mole mo;
Nko tun tan O ni suru mo;
di Nko fa ‘binu Re l’ese mo,
p Nko dese si ife Re mo.

2. mf Jesu, b’anu mbe lodo Re,


Da gbogbo re le mi lori;
cr Emi olori elese,
T’o nm’imi-edun f’anu Re,
Mu mi bo s’or’-ofe Baba,
Ma jeki mbi O ninu mo.

3. f Orisun ife ti ki gbe,


Jesu Abanikedun, gbo;
Olugbala mi li oke,
cr S’Alagbawi mi l’ekan si,
F’igbagbo on ‘fiji fun mi;
mp Jo jeki nyipada, ki nye!
Amin.
250
L.M.
Emi o fe O, Oluwa agbara mi. O.D. 18:1.

1. mf Olorun, kil’emi y’o mu


Wa fi wole niwaju Re?
Kini uno ti ri loju Re?
Kini uno mu wa gb’or’-ofe?

2. cr Eni nfe oju rere Re


Ko le se lairin lona Re;
K’o fe oto ati anu,
K’o f’igbagbo b’Olorun rin.

3. Mba je Tire lat’oni lo,


Ese mi atijo si mbe;
Bi mo f’ohun gbogbo fun O
Tire ni mo fun O pada.

4. mf Nje, kini mo le igbekele?


Nko l’ohun kan, asan ni mi,
Gbogbo fuja mi l’a sati
Itiju gbe ogo mi mi.

5. cr Mo j’elebi niwaju Re,


Lori mi n’binu Re mbe;
p O to k’a je mi ni iya;
Oto; sugbon Jesu ti ku!

6. cr Jesu ti ta ‘je Re sile,


O ru ese wa lor’igi;
mp O teriba lab’egun wa;
p O pari! O ti ku fun mi.

7. cr Wo t’o duro niwaju ‘te


O ngbadura ti y’o bori
O nf’iha, at’owo Re han,
Pe, a ko ‘ruko mi sibe.

8. O mbe laelae lati bebe;


Pe ki nle joba pelu Re
f Amin s’eyi t’Oluwa wi!
ff Jesu ki O bebe lasan.
Amin
251
8.8.8.D.
Tali Olorun bi Iwo ti o ndari aisedede ji. Mika 7:18.

1. mf Olorun ‘yanu ogo Re,


Nhan ninu gbogbo ise Re,
Sugbon or’ofe ‘dariji,
Jije ohun iyanu julo.
Olorun tani dabi Re,
Ore tani po bi Tire?

2. mpN’iyanu at’ayo l’a gba


Idariji Olorun wa,
‘Dariji f’ese to tobi
T’eje Jesu s’etutu fun,
Olorun tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?

3. cr ‘Dariji lat’ow’Olorun
‘Dariji fese to tobi
‘Dariji ni p’eje Jesu
‘Dariji m’olote wa ‘le
Olorun, tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?

4. p Jo, je k’ore-ofe Re yi,


Ife iyanu nla Re yi
cr Fi iyin kun gbogbo aye
Bi t’egbe akorin l’oke
Olorun, tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?
Amin.
252
L.M. & Ref.
Ibukun ni fun awon ti a dari aisedede won ji, ti a si bo ese won mole. O.D. 32:1.

1. mf Ero didun ni t’ese mi


T’a sin s’abe omi okun
‘Gbati agbara Olorun
Dide fun ‘gbala okan mi.
f “Iwo yoo ran ese won lo s’ogbun okun,”
Ileri Oluwa ni, o si to fun mi
B’omi okun tile nho pelu bibi re
Y’o rele, y’o si gbe, ko le de odo mi
Nitori Olorun nikan l’o kawo igbi-
Omi nla ti ‘nu okun.

2. mf Won ki y’o tun gb’ogun ti mi,


Tabi yo okan mi lenu,
cr ‘Tori agbara Olorun
Ni y’o mu idariji wa.

3. mf Ko si wahala to le mu
Ese mi wa si iranti,
f Okan mi s’owon l’oju Re,
Y’o d’abobo nigbagbogbo
. Amin.
253
7.6.7.7. & Ref.
Bi iwo ba rewesi li ojo iponju, agbara re ko to nkan. Owe 24:10.

1. mf Mo gbo Jesu wipe


“Agbara re kere”
Alare, sora, gbadua,
Pipe re mbe lodo mi.
f Jesu san gbogbo
‘Gbese ti mo je,
Ese to m’abawon wa
Lo ti fo nu kuro.

2. cr Oluwa, toto mo mo
P’agbara Re nikan
Le s’adete di mimo,
O le m’okan lile ro.

3. Ko si ‘re ‘kan ti mo ni
Lati ni ore Re,
Em’o fo aso mi mo
N’n’eje Jesu Oluwa.

4. p Gbati ‘pe ‘keyin ba dun


T’o n pe mi s’odo Re,
Jesu ti san gbogbo re,
Em’o ba gb’oke orun.

5. cr N’iwaju ‘te uno duro


N’nu pipe ewa Kristi
Uno fi ade ogo ni
Lele li ese Jesu.
Amin.
254
C.M.
Isun kan yio si sile fun ese ati iwa aimo Sek. 13:1

1. mf Isun kan wa to kun f’eje


T’o ti ‘ha Jesu yo,
Elese mokun ninu re
O bo ninu ebi.

2. mp‘Gba mo f’igbagbo r’isun na


Ti nsan fun eje Re,
Irapada d’orin fun mi
Ti un o ma ko titi.
3 f Orin t’odun ju eyi lo
Li emi o ma ko:
‘Gbati ore-ofe Re ba
Mu mi de odo Re.

4. mfMo gbagbo p’o pese fun mi


Bi mo tile s’aiye,
Ebun ofe t’a f’eje ra
Ati duru wura.

5. Duru t’a t’ow’Olorun se,


Ti ko ni baje lae,
Ti ao ma fi yin Baba wa
Oruko Re nikan
. Amin
255
7.6.7.6.D. & Ref.
Eyi ha ise akoko ati gba fadaka ati lati gba aso. IIA. Oba 5:26.

1. mf A ko fi oro ra mi,
Fadaka on wura,
Un o jijakadi f’orun,
Un o si wo ‘nu agbo;
N’nu iwe Ijoba Re
Ti o l’ewa pupo,
So fun mi Oluwa mi,
Oko mi ha wa nbe?
cr Oko mi ha wa nbe?
Ninu iwe nla ni
Iwe ti Ijoba Re
Oko mi ha wa nbe?

2 cr Oluwa, ese mi po,


Bi iyanrin okun,
Sugbon eje Re, Jesu
Ti to fun gbogbo re,
‘Tori ‘Wo ti se ‘leri
Ninu oro Re pe;
‘’B’ese re pon b’ododo,
Un o fo won fun bi sno.’’

3 f N’ilu daradara ni
At’ opo ‘bugbe Re,
Nibit’ awon mimo wa
Nin’aso funfun won,
T’ohun eri ko le de
Lati b’ewa re je
‘Bi t’awon angeli nso,
Oko mi ha wa nbe?
Amin.
256
L.M
Bere ohun ti Emi o fi fun o I A. Oba 3:5.

1 mf Oluwa, Iwo ha wipe


Ki mbere ohun ti mo fe
Jo, je ki mbo lowo ebi,
Ati low’ese on esu.

2 cr Jo, fi ara Re han fun mi,


Si je ki nru aworan Re,
Te ite Re si okan mi,
Si ma nikan joba nibe,

3 mf Jeki nmo p’O dariji mi,


Ki ayo Re s’agbara mi,
f Ki nmo giga , ibu , jinjin,
Ati gigaun ife nla Re.

4. cr Eyi nikan niebe mi


Eyi t’o ku di owo Re.
pp Iye, iku , aini , oro
cr Ko je nkan b’oba je t;emi
. Amin.
257
C.M
Awon ti o gba opolopo ore ofe atiebun ododo yio joba ninu iye. Rom. 5:17

1. f O re-ofe b’ o ti dun to
T’o gba em’ abosi;
cr Mo ti sonu, O wa mi ri,
O si si mi loju.

2. cr Ore-ofe ko mi ki m’ beru,
O si l’ eru mi lo
B’ ore –ofe na ti han to
Nigba mo ko gbagbo .

3. mf Opo ewu at’ idakun


Ni mo ti la koja;
f Or’-ofe npa mi mo doni
Y’o ju ‘gba ‘saju lo.

4. f Leyin aimoye odun n’ be


T’ a si nran bi orun ,
Gbogb’ ojo tao fi ‘yin Re
Y’o ju ‘gba saju lo.
Amin.
258
7.7.7.7.D.
Oluwa odo Re ni mo sa pamo si OD.143:9

1. mpJesu Olu’f’ okan mi,


Je ki nsala s’ aya Re,
cr Sa t’ irumi sunmo mi.
Sa ti iji nfe soke;
mf Pa mi mo, Olugbala
Tit’ iji aye y’opin,
di To mi los’ ebute Re,
p Nikeyin, gba okan mi.

2. mf Abo mi, emi ko ni,


Iwo l’ okan mi ro mo;
di Ma f’ emi nikan sile;
Gba, mi si tu mi ninu,
mf Ma sai f’ iye apa Re.
Dabo b’ori aibo mi.

3. mf Krist’Wo nikan ni mo fe;


N’nu Re mo r’ohun gbogbo
Gb’ eni to subu dide,
W’alasian to afoju,
Ododo l’ oruko Re
p Alais’ ododo l’emi
Mo kun fun ese pupo,
mf Iwo kun fun ododo.

4. cr Wo’ l’opo ore-ofe,


Lati fi bo ese mi;
Je ki omi iwosan
We inu okan mi mo;
f Iwo l’ orisun iye,
Je ki mbu n’nu l’ofe,
Ru jade n’nu okan mi,
Si iye ainipekun
. Amin.
259
9.8.9.8.& Ref.
E ma yo ninu Oluwa nigba gbogbo, mo si tun wi, “E ma yo.” Fili. 4:4.

1. Okan mi yo ninu Oluwa


‘Tori o je iye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo
Adun ni lati r’oju Re
Emi yo ninu Re
‘Gbagbogbo l’o nfi ayo kun okan mi
‘Tori emi yo ninu re.

2. O ti wa mi pe k nto mo o
‘Gbati mo rin jina s’agbo
O gbe mi wa sile l’apa Re
Nibiti papa tutu wa
Emi yo ninu Re
‘Gbagbogbo lo nfi ayo kun okan mi
‘Tori emi yo ninu Re.

3. Ore at’anu re yi mi ka
Or’ofe re nsan bi odo
Emi re nto, o si nse ‘tunu.
O ba mi lo sibikibi
Emi yo ninu re
‘Gbagbogbo lo nfi ayo kun okan mi
‘Tori emi yo ninu Re.

4. Emi y’o dabi re n’ ijo kan,


O s’eru wuro mi kale,
Titi di ‘gbana ngo j’ oloto
Ni sise oso f’ ade Re Amin.
Emi yo ninu re
‘Gbagbogbo lo nfi ayo kun okan mi
‘Tori emi yo ninu Re
. Amin
260
6.6.6.6 8.8
Awon ni alagbawi kan lodo Baba, Jesu kristi olododo. I Jn.2:1

1. f Dide, emi mi, nde


Gbon eru ebi re,
Eni t’ a pa fun mi,
F’ arahan n’ tori mi;
Mo l’ onigbowo n’ idi te,
A ko’ ruko mi s’ owo Re.

2. f O mbe l’oke laelae


Lati bebe fun mi.
On nf’ ife’ rapada
At’ eje Re bebe,
di Eje Re se ‘ tu gbogb’aye
O mbu won ite or’ofe.

3. p Ogbe marun l’o gba


Li oke kalfari;
cr Won ngbadura aitase,
Won mbebe n’tori mi,
p Won nke, Dariji, dariji’
Ma je k’elese na ko ku

4. mp Baba gb’ ebe eni


Ami ororo Rre,
Ko le ko adura
Ti omo Re owon,
Emi Re ndahun ebe na
Pe, mo d’ atunbi, Olorun’

5. mf Mo b’Olorun laja,
cr Mo gb’ohun fiji Re,
O si mi d’ omo Re,
Emi ko beru mo;
f Mo fi gboya sunmo do’ Re,
Mo si nke pe, Abba Baba’
Amin.
261
Ore ofe Jesu Kristi Oluwa ki o pelu yin 1Kor. 16:23

1. f Ore ofe, ohun


Adun ni leti wa
Gbohun gbohun re yo gba orun kan
Aye yo gbo pelu
ff Ore ofe sa
N’igbekele mi
p Jesu ku fun araye
ppO ku fun mi pelu.

2. f Ore ofe lo ko
Oruko mi lorun;
Lo fi mi fun odagutan
To gba iya mi je.

3 mp.Ore-ofe to mi
S’ona alafia;
O ntoju mi lojoojumo,
Ni irin ajo mi.

4 .mfOre ofe ko mi
Bi a ti ‘gbadura;
cr O pa mi mo titi d’oni
Ko si je ki nsako.

5. f Je k’ore ofe yi
F’agbara f’okan mi
mf Ki nle fi gbogbo ipa mi
A t’ojo mi fun o
Amin
262
D.L.S.M

1. mf Ajigbese opo anu,


Un o korin Iyin anu Re,
f Aso ododo Olorun
Ni mo gbe wo; eru ko si;
Ofin ko le da mi l’ ebi,
Ore-ofe so mi d’ Ominira,
Igboran Olugbala mi,
At’ eje Rrwe, bo ese mi.

2. f ise rere t’o ti bere,


Apa Re y’o se l’ asepe;
Gbogbo ileri rere Re,
Beni amin ni titi lae;
mf Tani le ya wa ninu krist’
Ko si l’aye, ko si l’orun
T’o le mu ipinu Re ye.

2. f Oruko mi mbe lowo Re


Nko r’ eni ti o le pare,
Ami or’ofe lara aya mi,
Mo wa li okan aya Re;’
Un o foriti titi d’ opin,
Mo d’ ohun ini Olorun ,
Ayo orun mbe l’ okan mi,
Oel’ awon t;’ a ti l’ ogo.
Amin.
263
9. 7. 9. 7. 7c Ref.
Eyin si nyo ayo ti a ko le fi enu so ti o si kun fun ogo. 1st Pet. 1:8

1. cr Mo ti de ile ore-ofe
O to fun gbogb’aini mi
Nigbati mo joko l’ese Re
O si so mi d’ominira
f Ayo nla ni, ayo ti Jesu nfifun ni
Ayo ti enu ko le so
Ayo nla ni, ayo ti o kun fun ogo
Ayo ti a ko le royin tan.

2. f Mo ti de ile igbadun nla,


Alafia mbe ninu mi,
Ibukun ti o kunwosile
mp Mo bo l’owo ese mi.

3. cr Mo ti ni ireti t’o daju


Ninu ore-ofe Re,
Olugbala mi mbe pelu mi,
O nrerin si omo Re.

4. f Mo l’ayo ti enu ko le so,


Ogo ayo na npo si
Bi kanga om’iye ninu mi,
‘Jojumo l’o nru soke.
Amin
264
C.M
Olori Alufa to ba ni kedun ni inu ailera wa.Heb. 4:15

1. f Af’ ayo ro ore-ofe


T’ Alufa giga wa;
Okan Re kun iyonu;
Inu Re nyo fun ‘fe.

2. mpTinu –tinu l’ On daro wa,


O mo ailera wa;
O mo bi idanwo tui ri.

3. cr On papa lojo aye Re


p O sokun kikoro;
O mba Olukulu pin
Ninu iya ti nje.
4. mf Jek’a igbagbo, irele
W’ anu at’ ipa Re
Awa o si ri igbala
L’akoko iyonu
Amin.
265
L.M
Ibukun ni fun okunrin na ti o wa ogbon ri.Owe 3:13

1. f Alabukun l’eni t’ o ri
Ore-ofe Olorun gba,
Ogbon t’o t’oke sokale,
Igbagbo t’o nfi fe sise.

2. f Ibukun t’a ki le juwe


Ni t’eni mo ‘yi ‘ku Jesu,
Ebun t’a ko le f’enu so,
Oye orun y’o je tire.

3. mf Ogbon orun; tani le so


Iye owo t’a le fi ra?
Ogbon fuyi pupopupo
Ju fadaka on wura lo.

4. Emi gigun mbe lowo re,


Oro at’iyin ti kiku,
Oro Kristi t’a fi ji wa,
Pel’ola t’Olorun nfun wa.

5. f Ayo pipe l’O pe wa si


Pelu adun mimo gbogbo;
Ona didara l’ona Re,
Gbogbo ‘pa Re kun f’alafia.

6. ‘Bukun ni t’eni ri ogbom


T’o si di mu titi d’opin!
Ini rere ni tire lae;
Kristi, ogbon, at’orun j’okan.
Amin.
266
7.7.7.7.7.7.
Pa oju Re mo kuro lara ese mi ki iwo ki o si nu gbogbo aisedede mi nu kuro.
O.D. 51:9.

1. mf Jesu, f’oju anu Re,


Mu k’ibanuje mi tan;
Nibo l’elese ba lo?
Iwo l’Ore elese,
Mo fe wa ‘simi n’nu Re
Emi otos’elese.

2. mp Yara, jo yara gba mi!


Yo mi kuro n’nu ‘leru,
Gba mi lowo ese mi!
N’itor’ife at’anu Re;
S’okan mi di ominira
F’agbara Re han n’nu mi.

3. cr Emi otosi julo,


Alaimo at’eleri;
Emi t’o jinna si O,
T’o kun f’osi at’ese;
Fi ipa ife gba mi,
Ki o si dariji mi!

4. cr Jesu, l’oko Re nikan


Ni mo n’ireti ‘gbala,
Mo wa l’owo anu Re
Gba mi, gba mi la d’opin
F’opo or’-ofe fun mi,
Gba mi la s’orun mimo.
Amin.
267
7.6.7.6.7.6.D.
Awon oke nla ati awon oke kekeke yio bu si orin niwaju yin. Isa. 55:12.

1. f Gbogb’aye kun fun orin,


Mo ngbo nibi gbogbo;
Awon ‘tanna papa ndun
Layo n’nu afefe,
Loke, li ayika mi,
Orin jeje nyin lo
Oba ogo wa mi ri,
Orin wa n’n’okan mi!
mf Eje Jesu Kristi nsan,
Igbi Re yi mi ka;
Ife mole lokan mi,
Orin wa n’n’okan mi!

2. cr Teleri, imi efun


Li okan mi ma nfe;
Nitori ailera mi
Ni o se fi ri be
Nigba mo f’okan mi fun
Oro Re wo mi san,
Lae mo wa lodo Kristi
Orin wa n’n’okan mi!

3. mp Gbogb’aye mi ti kun fun,


‘Banuje at’aro;
Sugbon lat’isiyi lo
Ororo ayo de;
Adura d’orin iyin
Mo si wa nlepa nso
Ni adura at’ise
Orin wa n’n’okan mi!

4. f Beni okan mi si nyo


Si oro Oluwa;
Gbogbo ‘gba lo si nkorin
Gege b’awon eye;
Emi ko mo ibiti
Orin harp na ti ndun,
mp Mo mo p’orun sunmo mi,
f Orin wa n’n’okan mi.
Amin.
268
7.6.8.6.7.6.7.6.
Ore-ofe li a ti fi gba yin la nipa igbagbo. Efe. 2:8.

1. mpOr’ofe nipa ‘gbagbo


Lo so mi d’atunbi
Ki se nipa ‘se owo mi
mf Sugbon ti Kristi t’a pa;
N’nu Re mo d’eda titun,
‘Reti miran, asan;
Or’ofe nipa ‘gbagbo
Lo so mi d’atunbi

2. mpOr’ofe nipa ‘gbagbo


Lo gba mi low’ese;
f Eru ebi na ti fo lo;
Alafia wa njoba;
Sodo Krist’Olugbala
Un o ko asako lo;
Or’ofe nipa ‘gbagbo
Nikan lo gba mi la.

3. f Or’ofe nipa ‘gbagbo


Ayo ‘yanu n’temi!
Ebun ife orun fun mi
N’iye ainipekun;
Bi mo tile s’alaiye;
Ife Re ni mole mi;
Or’ofe nipa ‘gbagbo
Ayo ‘yanu n’temi.
Amin.
269
10.8.10.8.& Ref.
Isun kan yio si sile fun ese ati fun iwa aimo. Sek. 13:1.

1. mpMo ti de ‘bi orisun ‘wenumo


Mo ri sinu eje ti nsan
Jade lat’ori oke Kalfari
T’o m’okan mi di mimo lau.
f Daju okan mi di mimo;
Mo mo p’eje Kristi we mo
O si ngbe inu mi,
O mu k’okan mi di mimo.

2. mpMo ti de ‘bi orisun ‘wenumo


Alafia pipe je temi;
Nipa or’ofe O f’ese mi ji,
Alafia de ‘nu okan mi.

3. f Mo ti de ‘bi orisun ‘wenumo


Ogo si kun ‘nu okan mi;
ff Aleluya! Mo ni ayo kikun,
‘Tori mo di mimo laulau.
Amin.
270
10.10.10.10.& Ref.
Nigbati okan ninu won ri pe a mu on larada o pada, o si yin Olorun logo. Lk. 17:15.

1. mf Etutu eje Krist’ t’a ta sile,


mpLori ‘gi Kalfari l’o gba mi la,
Sugbon mo nfe isun to ju yi lo
Ekun ibukun Rre l’okan mi nfe lati mo.
fMo ngba l’aye bi l’orun,
Mo f’aye mi fun Jesu,
Mo l’ayo ninu ominira ti O fun mi;
Oro na ti On ti so
Ti ja gbogbo ide mi;
‘Seju kokan aye mi si je
‘Bukun orun.

2. f T’emi l’ayo lat’orisun ife,


Ebun orun yi lo wu mi julo,
Mo si wa ni alafia pipe
Nigbati emi Re fun mi l’oro ominira.

3. mf Iwo f mo ekun ore Baba?


Iwo fe gbe n’nu ibu oro Re?
f Gbagbo; ileri Re otito ni;
Si gba ominira t’o ni ‘bukun t’O fi fun o.
Amin.
271
10.9.10.9.D.
Nigbati awa je elese, Kristi ku fun wa. Rom. 5:8.

1. mf Lekan mo wa ninu ide ese,


Bi eru nko si le ja ‘jabo;
f Sugbon mo ri idande ologo,
Gba Jjesu ja ide mi sonu.
f Ominira ologo at’iyanu
Nko si ninu ide ese mo,
Jesu Oludande at’ologo
Y’o je t’emi loni, titi lae.

2. mp Omnira kuro n’nu ife ara,


Owu, ikorira on ija;
Omnira kuro n’nu asan aye
Ati gbogbo ikoro aye.

3. mf Omnira low’ese igberaga,


Ife owo egbin on wura,
Ero ibi at’oro ibinu
Omnira ayo at’ologo.

4. f Omnira lowo ‘beru on ‘rora,


Lowo aniyan at’edun re,
Omnira n’nu Krist’ Olurapada
Eni t’O ja ide mi sonu.
Amin.
272
6.6.10.D. & Ref.
Ki a si gbe Olorun igbala mi soke. O.D. 18:46.

1. f Gba Jesu wo mi san


N’ife Re han si mi;
Gbogb’ese mi l’Olugbala ko lo
Ayo yi po pupo
B’igbi n’nu okan mi,
Beni ‘fe na nposi lojojumo,
f Be n’ife na npo si lojojumo
Mo fe ona toro t’atijo ni;
Ayo kun okan mi
Gba Jesu wo mi san,
Be n’ife na npo si lojojumo.

2. mp Mo fi ese sile,
Aye at’ogo re,
Nisiyi, mo wa l’ona didara,
Mo si ni alafia,
mf Mo bo lowo ‘foya,
Be n’ife na npo si lojojumo

3. f Un o sin l’aye yi,


B’aye tile nfo lo,
Laipe Oluwa yo de n’nu ogo;
ff Eyi mo mo daju,
Ti nmu inu mi dun;
Ife Re npo si ninu okan mi.
Amin.
273
12.11.12.12.& Ref.
Enikeni ti o ba to mi wa, Emi ki yio taa nu bi o ti wu ki o ri. Jn. 6:37.

1. mf ‘Gba mo t’Oba mi wa pelu okan tite,


Ti mo mbebe f’or’ofe n’iwaju ‘te Re,
f Ayo ti mo ri l’oju Re, bo ti dun to!
B’ayaba Esther, O n’opa anu si mi.
ff Opa ife loje ati t’idariji,
L’ofe si ni opa anu na,
Oba orun b’oju wo ‘le lat’oke
O si na opa na si mi.

2. mp Mo ti sako jina to ninu ese mi;


Ninu ope mo ti padanu pupo,
cr Mo so ‘reti nu ‘gbat’o ku emi nikan,
Mo gb’ohun adun Re, sunmo ‘te mimo.

3. cr Bi ’wo ba je le f’okan re fun Krist’ Oba


Y’o fi se ‘le, ko si ni kuro nibe,
f Sa ronupiwada, ayo y’o je tire,
Nitori Jesu y’O n’opa ani si o.
Amin.
274
11.11.11.11.& Ref.
Olufe mi ni temi, emi si ni Tire. O. Sol. 2:16.

1. mf Lekan mo nwa ‘bukun, ‘wosan ore Re


Nisiyi, Olorun papa ni mo nfe,
Oluwa funrare t’is’Olubukun
Nikansoso ni mo nfe nisisiyi.
ff Jesu! Jesu! Jesu!
L’em’o ko titi;
Gbogb’ohun ti mo nfe
Ni mo ri ninu Re.

2. cr Lekan mo ngbiyanju laini igbala,


Nisisiyi mo ni igbala pipe;
Laini ‘gbagbo ‘gbi aye ngba mi kiri,
On ti di mi mu, ‘dakoro mi ko ye.

3. mp Lekan mo ns’aniyan, mo nsiyemeji;


Lekan mo nyan le Oluwa mi lowo,
Lekan mo nsi bere ninu adura,
Ife Jesu nikan ni sise loni.

4. mf Lekan, mo n’ireti n’nu ‘se owo mi,


Lekan, mo nfe aye ati ogo re,
Lekan, ife ti inu mi ni mo nse,
Loni mo d’ohun elo fun Oluwa.

5. Mo ti nreti Jesu, loni t’emi ni;


Lekan, mo ngbe oku igbagbo kiri,
Lekan, emi ko ni ireti iye,
Nisiyi bibo Re je ayo fun mi.
Amin.
275
10.10.9.9.& Ref.
Ore-ofe li a fi gba yin la. Efe. 2:8.

1. mf Ninu aini ni mo to Jesu wa,


Ore-ofe Re lo da mi l’ola,
cr Nko je gberaga, nko je hale,
Ore-ofe Re lo gba mi la.
mp Ore-ofe lo gba mi la.
Ore-ofe lo gba mi la.
f Eyi l’oro na, Ogo ni f’Olorun;
Ore-ofe Re lo gba mi la.

2. mf Lekan ese ti njoba l’okan mi,


Mo sako jinna lodo Oluwa,
Jesu wa mi ri, mo ti l’ayo,
Ore-ofe Re lo gba mi la.

3. mp Ekun ko le mu ‘re kan wa fun mi,


Anu Re nikan lo fi gba mi la,
cr Ese ti mu ki nma beru ri,
Sugbon or’-ofe ti gba mi la.

4. mf Je ki elese t’ago re ti kun,


So ife Olugbala re kiri,
Un o ma tun itan na so titi,
Ore-ofe Re lo gba mi la.
Amin.
276
S.M.
Okan mi nfa nitoto, o tile pe ongbe fun agbala Oluwa:
aya mi ati ara mi nkigbe si Olorun alaye. OD. 84:2.

1. p ‘Wo Oluwa oke,


Ati abe sanma;
Mo dobale li ese Re,
Mo nke fun anu Re.

2. p Dari ‘were ji mi
Ese ti mo ti da;
So fun okan ofo, po ye
Nip’Omo bibi Rre.

3. p Ebi, bi eru nla


Wa l’ori okan mi
Iwo ni mo ro edun fun,
‘Wo ni mo sokun ba.

4. Inira ti eru nla


‘wo l’ori oksn mi.
Oluwa f’idariji han,
At’ opo ife Re.

5 p Oju anu re kan


Ko f’aya mi bale.
Je ki nmo pe a darijji mi,
Un o dala bukun fun
Amin
277
C.M.
Bikosepe a tun eniyan bi nipa omi ati nipa Emi on ki yoo le wo ijoba Olorun Jn.3:5.

1 f Eyi lase nla Jehofa


Yoo wa titi lae
Elese b’iwo at’emi,
K’a tun gbogbo wa bi.

2 p Okunkun y’o je ipa wa,


B’a wa ninu ese;
Aki o ri ijobs Re,,
Bi a ko tun wa bi.

3 Bi baptisi.wa je ‘gbarun,
Asan ni gbogbo re
Eyi ko le ese wa mu,
Bi a ko tun wa bi.

4 Wo ise were ti a nse,


Ko ni iranwo Re;
Won ko s’okan wa di otun,
B’awa ko datunbi.

5 f Lo kuro ninu ese re


cr Ja ewon Esu nu;
f Gba Krist gbo tokantokan
ff Iwo o datunbi
Amin
278
C.M.
Omokonrin,tujuka, a dari ese re ji. Mat.9:2.

1 p Ebi ese npa mi l’eru,


O te ori mi ba,
Oluwa fi okan eran
Paro t’okuta mi

2 Mo de, eru ese npa mi,


Iku mba mi l’eru;
Feje Re te dariji mi,
Si le eru mi lo.

3 Okan mi ke le r’isimi
titi un o fi kigbe
p Li abe agbelebu Re,
Pe,”Jesu ku fun mi,”

4 Fun mi lati ni igbagbo


Ati iriri yi,
Titi iwa ogbo yoo lo,
T’okan mi yoo d’otun.
Amin
279.
L.M
Awon omo lsreal si wi fun Oluwa pe, Awa ti se; ohunkohun ti o
ba to li oju re ni ki o fi wa se: sa gba wa li oni yi, awa be o A.Oni.10:15

1 p Oluwa, sanu, dariji;


Da okan t’oyipada si
Ki se pe anu Re tobi
Elese ko le ro mo O?

2 Ese mi po, sugbon ko le


Ju agbara ore Re lo:
Titobi Re ko ni opin,
Be ge ni k’ari ife Re.

3 p We ese kuro l’okan mi,


Si mu okan ebi mi mo;
Lokan mi ni eru na wa,
Ese ehin ro mi l’oju.

4 Ese mi fitiju jewo


Ete s’ofin at’ore Re:
Bi idajo Re yoo ba le,
Mo jebi, ae ni Tire.

5 p B’idajo kankan gbemi mi,


Loju ku un o da O l’are,
B’a si ran mi lo siparun
Tito ni loju ofin Re.

6 Sibe, gba e;ese t’o ngbo,


Ti ireti re nran baba,
Bi o le r’ileri didun
Lai ba le n'nu oro Re
Amin
280
C.M
Olrun sanu fun mi elese Lk 18;13
1 mf Oluwa b’agbowode ni,
Mo gb’okan mi le O;
Oluwa, f’ore-ofe wi.
p K’o se anu fun mi.

2 mf Mo lu aiduro aya mi,


p Ekun at’irora;
K’o gb’okan mi ‘nu irora,
p K’o se anu fun mi.

3 N’itiju mo jew’ese mi,


Jo fun mi n’ireti;
Mo be,’tori eje Jesu,
K’o se anu fun mi.

4 Olori elese ni mi,


Ese mi papoju;
Nitori iku Jesu wa,
p K’o se anu fun mi

5 Mo duro ti agbelebu,
Nko sa f’ojiji re:
Ti Olru t’o po lanu,
p O ti anu fun mi
Amin
281
S.M
Wa, eniyan mi.Isa.26:20

1 f Baba wa orun npe,


Krist;npe wa sodo re;
Ore wa pelu won o dun,
‘Dapo wa y’o s’owon.

2 mp Olorun nkanu mi;


O dar’ese mi ji,
Olodumare s’okan mi,
O f’ogbon to’pa mi.

3 p Ebun Rew ti po to!


Ol’opo isura,
T’a t’owo Olugbala pin,
Ti a f’eje Re ra!.

4 f Jesu Ori’ye mi,


Mo fi bunkun fun O;
Alagbawi lodo Baba,
Asaju lodo Re.

5 Okan at’ife mi,


E duro je nihin;
Titi’ dapo yoo fi kun
L’oke orun l’ohun
Amin
282
S.M
Emi korira ara mi, mo si ronupiwada se toto ninu ekuru ati eru. Job. 42:6

1. Alaimo ni emi,
Olorun Oluwa
Emi ha gbodo sunmo O
T’emi t’eru ese.

2. Eru ese yi npa


Okan buburu mi,
Yio ha si ti buru to
L’oju Re mimo ni!.

3. Emi o ha si ku
Ni alainireti
Mo r’ayo ninu iku Re
Fun otosi b’emi.

4. Eje ni ti a ta
T’ise or’ofe Re;
Le w’elese t’o buruju
Le m’okan lile ro.

5. pp Mo wole l’ese Re
Jo k’o dariji mi
Nihin l’emi o wa titi
‘Wo o wipe, “Dide”
. Amin
283
8.8.7.&.Ref
Eyin to ti jina nigba atijo ri li a mu yin sunmo tosi nipa eje krist.Efe.2:13

1 mf Lekan, mo jina s’oluwa


Mo nfi ‘wa mi bi ninu
Sgbon Jesu ti gba mi
A ! bi yo ti dun to
Dun to dun to dun to
A ! bi yo ti dun to
Ki Jesu ma gbe inu mi.

2 mp Ibinu ati irunu


Ni ewon t’esu fi de mi
Jesu ti ja ide na.

3 cr Ifekufe kun okan mi


Ati igberaga gbogbo
Ina Emi ti yi Oluwa.

4 f Mo bo lowo irewesi
Lowo’ko gbona ko tutu
ff E ba mi yin Oluwa.

5 f Mo nkorin sa lojojumo
Mo njo mo si tun nfo soke
Nipa agbara Emi

6 mf Eje’ yebiye we mi mo
Omi iye nsan ninu mi,
f Igbala mi di kikun.

7 f Eyin ara at’ore mi


tani ko fe igbala yi
Ofe ni lodo Jesu;
Amin
284
C.M
IIsun kan yio si sile fun ese ati iwa aimo Sek.13;1

1 mf Isun kan wa to kun f’eje,


T’o ti ‘ha Jesu yo;
mpElese mokun ninu re,
O bo ninu ebi.
mf A sa l’ogbe,n’tori’rekoja,
A si pa ;ara, n’tori ese wa,
cr Ina alafia wa mbe l’ara Re
mf Ina Re lo now wa san;
mp A sa l’ogbe n’tori’Rekoja,
A sa l’ogbe n’tori’Rekoja,
ff Ina Re lo now wa san
mf Ina Re lo now wa san

2 p Ole ni lor’agbelebu,
mf Yo lati ri ‘sun na,
mp Bi mo kun f’ese bi tire,
cr Mo le we n’n’eje na.

3 mf ‘Gbamo figbagbo risun na


cr Ti nsan fun eje Re
f Irapada d’orin fun mi.
Ti un o ma ko titi.

4 f Agbara to wa n’n’eje yi
Yo wa titi laelae,
ff Tit’awaon eni ‘rappada,
Yo bo sinu ogo. Amin
285
C.M. & Ref.
O fi orin titun si mi li enu. OD. 40:3.

1. f Mo ni orin kan ti mo fe,


Gbat’ O ra mi pada:
T’Olurapada, Oba mi,
Gbat’ O ra mi pada.
mf Gbat’ O ra mi pada
Gbat’ O ra mi pada
ff Un o s’ ogo n’nu oko Re,
Gbat’ O ra mi pada;
Un o s’ogo n’n’ oko Olugbala.

2. f Mo ni Kristi t’O to fun mi,


mp Gbat’ O ra mi pada;
Sise ‘fe Re, ‘yebiye ni,
Gbat’ O ra mi pada.

3. mf Mo ni eri nin’ okan mi,


Gbat’ O ra mi pada;
O le ‘yemeji, eru lo,
Gbat’ O ra mi pada.

4. ff Mo ni ayo ti nko le so,


Gbat’ O ra mi pada:
mf Nipa eje to nwe mi mo,
Gbat’ O ra mi pada.

5. mf O pese ‘bugbe kan fun mi,


Gbat’ O ra mi pada.
Nibi un o gbe tit’ aye,
Gbat’ O ra mi pada.
Amin.
286
7.6.7.6s
Wo o! emi duro tii lekun emi si nkankun. Ifi. 3:20.

1. mpA! Jesu, Iwo nduro,


Lode, leyin ‘lekun;
Iwo fi suru duro
Lati koja sile:
cr ‘Tiju ni fun wa, Kristian,
Awa ti nj’oko Re!
Itiju gidigidi,
p B’a ba jo Re sode.

2. mf A! Jesu, Iwo nkankun,


Owo na si l’apa;
Egun yi ori Re ka,
Ekun b’oju Re je:
cr A! ife ‘yanu l’eyi,
T’o nfi suru duro!
di A! ese ti ko l’egbe,
T’o ha ‘lekun pinpin!

3. p A! Jesu, Iwo mbebe


Lohun pelepele,
pp “Mo ku f’eyin omo mi
Bayi l’e se mi si?”
mf Oluwa, a silekun
N’ikanu on ‘tiju!
cr Olugbala, wa wole
Ma fi wa sile lo
. Amin.
287
L.M.
Ati ninu olanla Re ma gesin lo.
OD. 45:4.

1. f Ma g’esin lo l’olanla Re,


Gbo! gbogb’aye nke,
“Hosana”
mpOlugbala, Ma lo pele
Lori im’ope at’aso.

2 .f Ma g’esin lo l’olanla Re,


p Ma f’irele g’esin lo ku;
cr Kristi, ‘segun Re bere na
f Lori ese ati iku.

3. f Ma g’esin lo l’olanla Re,


di Ogun angeli lat’orun
p Nf’iyanu pelu ikanu
Wo ebo to sunmole yi.

4. f Ma g’esin lo l’olanla Re,


mf Ija ikehin na de tan,
f Baba lor’ite Re lorun
Nreti ayanfe Omo Re.

5. f Ma g’esin lo l’olanla Re,


p Ma f’irele g’esin lo ku,
p F’ara da irora f’eda,
f Leyin na nde, k’O ma joba.
Amin.
288
10.7.10.7.
Hosanna fun omo Dafidi. MAt. 21:9.

1. ff Gbogb’ogo, iyin, ola


Fun O Oludande,
S’Eni t’awon omode
Nko Hosanna didun!

2. ff Egbe awon Maleka


Nyin O l’oke giga;
Awa at’eda gbogbo
Si dapo gbe ‘rin na.

3 . f Awon Hebru lo s’aju


Pelu imo ope;
Iyin, adua at’ orin
L’a mu wa ‘waju Re.

4. mf Si O s’aju iya Re,


Won korin iyin won!
‘Wo t’a gbega nisiyi
L’a nkorin iyin si.

5. cr ‘Wo gba orin iyin won,


Gb’adura t’a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ohun rere,
Oba wa Olore.
Amin.
289
7.7.7.7.& Ref.
Lati enu awon omo owo ati omo omu ni Iwo ti mu iyin pe. Mat. 21:16.

1. mf Awon ewe Salemu,


f Korin yin oko Jesu,
Awa ewe t’isiyi,
Jumo yin Olugbala
f Gbo, b’awon ewe ti nko
Hosana si Oba wa.

2. mf A ko wa k’a f’Oluwa,
K’a si ma ka oro Re,
cr A f’ona orun han wa!
f Ogo ni fun Olorun!

3. f K’oluko, t’agba t’ewe,


Jumo gbe orin na ga,
ff Loke-loke, k’o ma ho
Ki Hosana de orun.
Amin.
290
8.8.8.D.
Yo gidigidi, iwo omobirin Sioni, ho, iwo omobinrin Jerusalem,
kiyesi Oba re mbo wa sodo re. Sek. 9:9.

1. f Iyin, ope at’olanla


Fun Jesu Kristi Oluwa;
Awon ‘mode nke Hosana
‘Gba Jesu gun ketekete,
Hosana l’orin wa loni,
Jesu, jowo gba iyin wa.]

2. mf A te aso at’imo ‘pe


S’ona fun Oba Israel;
O wo Salemu ni ‘rele,
W’Oba lori ketekete,
‘Wo to we Tempili ni mo,
Gba iyin ati ope wa.

3. ff Hosana s’Omo Dafidi,


Hosana, e korin didun
S’Oba to mu ipo ‘rele,
T’O wa s’aye l’awo eda
Fun ise ‘gbala iran wa;
Jesu, jowo gba iyin wa.

4. mp A ba le ri bi On tiri,
A ba le wa bi On ti wa,
K’agberaga re ‘ra sile
mf Ki ise Jesu lori wa
Le so wa di omo ‘mole
Ki iyin Re le ma po si.

5. f Jesu Mimo, Iwo l’a yin,


We wa mo bi Tempili Rre,
We egbin okan wa kuro,
Je k’a mo riri ise Re
Ki lala Re ma ba j’asan;
Si mu wa de ibi iye.
Amin.
291
10.7.10.7. & Ref.
Hosanna fun Omo Dafidi. Mat. 21:9.

1. f “Hosana s’Omo Dafidi:”


ff Hosana! e korin!
“Olubukun l’ Eni ti mbo
Loruko Oluwa”.

2 . f “Hosana s’Omo Dafidi”:


L’egbe Angeli nke;
ff Gbogb’eda, e jumo gberin,
Hosana! s’Oba wa.

3. Hosana! awon Heberu


Ja im’ope s’ona;
Hosana! a mu ebun wa
Fi tun ona Re se.

4. ff T’agba t’ewe nke, Hosana!


p K’ijiya Re to de;
L’oni, a si nko Hosana!
B’o ti njoba loke.

5 . B’o ti gba ‘yin won nigbana,


p Jo, gba ebe wa yi!
Lorun, k’a le b’Angel’ korin,
ff Hosana s’Oba wa.
Amin.
292
9.8.9.8.& Ref.
Nitori irapada okan won iyebiye ni. OD. 49:8.

1. f Irapada! Itan iyanu,


Ihin ayo fun gbogbo wa,
Jesu ti ra ‘dariji fun wa,
O san ‘gbese na lor’igi.
ff A! elese gba ihin na gbo,
Jo gba ihin oto na gbo,
Gbeke re le Olugbala re
T’O mu igbala fun o wa.

2. mpO mu wa t’inu ‘ku bo si ‘ye,


O si so wa d’om’Olorun;
cr Orisun kan si fun elese
We nin’eje na ko si mo.

3. f Ese ki y’o le joba wa mo


B’o ti wu ko dan wa wo to;
Nitori Kristi fi ‘rapada
Pa ‘gbara ese run fun wa.

4. f Gba anu t’Olorun fi lo o,


Sa wa s’odo Jesu loni;
‘Tori y’o gb’enit’o ba t’o wa,
Ki yi o si da pada lae.
Amin.
293
11.8.11.9.& Ref.
Won o ma wo eniti a gun li oko. Jn. 19:37.

1. mf ‘Gba ‘ba fe ya mi kuro lod’Oluwa,


Mo ranti ‘gi Kalfari ni;
cr Nibi Jesu jiya fun ‘rapada mi
At’okan t’a gun l’oko fun mi.
p Fun mi elese, b’emi, b’emi
A gun U l’oko fun mi;
Mo fi ‘gbagbo ri ni Kalfari:
Okan t’a gun l’oko fun mi.

2. mp Ore je eleke. On je Oloto,


mf Ife Re pe, ofe si ni
p Mo sokun ‘gba mo ri ‘ra mi nin’ese,
cr At’okan t’a gun l’oko fun mi.

3. mf Etutu mimo l’O ti f’eje Re se,


Un o ma so itan na titi;
Itan ti Jesu Olurapada mi
At’okan t’a gun l’oko fun mi.
Amin
294
9.6.10.7.& Rref.
Won kigbe wipe, kan a mo agbelebu. Jn. 19:6.

1. mpO ti ka itan agbelebu,


Nibiti Jesu ku;
Nibiti eje Re iyebiye
Ti san gbogbo gbese re?
pp O ku iku ‘banuje fun o,
O ku iku ‘banuje
mf A! ife iyanu fun o,
cr O ku iku ‘banuje

2. mf O ti ka b’a ti f’ade egun


De ori Re fun o;
mp‘Gbat’O gbadura pe, “Dariji won
Won se laimokan sa ni.

3. mf O ti ka b’O ti gb’ole ni la
T’o n ku lo lor’igi;
cr Nigbati o fi ikanu wipe,
mp“Oluwa, jo ranti mi”.

4. mf O ti ka b’O ti gb’oju soke


f T’O wipe, “O pari”
ff O ti so pe, “Mo dupe Oluwa,
cr Nitori O ku fun mi”.
Amin
295
8.8.8.D.
Eniti On tikara Re fi ara Rre ru ese wa lori igi. I Pet. 2:24.

1. f Olorun Olufe, kinla!


Eni aiku ti ‘ku fun mi
mf Omo ayeraye Baba
Ru gbogb’ese mi lor’igi;
cr Eni aiku ti ku fun mi;
Oluwa mi, l’a kan mo ‘gi.

2. mf Eyin ti nkoja lo, e wo


p B’eje ti nsan lara Jesu!
cr Elese wo, Eleda ku,
‘Banuje kan ri bayi ri?
mf Wa, k’a j’anfani eje Re;
Oluwa mi, l’a kan mo ‘gi.

3. mf A kan mo ‘gi fun gbogbo wa


K’a le pada t’Olorun lo;
E gba oto eri na gbo,
Pe, eje Jesu ti ra yin,
Lodo Re l’a le ri ‘fiji;
Oluwa mi, l’a kan mo ‘gi.

4. f Je k’a joko t’agbelebu,


mf Labe isun iwosan na,
K’a ka ohun gbogbo s’ofo
K’a fi gbogbo okan wa fun,
cr K’a ma ro eyi nikan pe,
Oluwa mi, l’a kan mo ‘gi.
Amin
296
7.7.7.D.
Kinla, enyin ko le ba mi sona ni wakati kan? Mat. 26:40.

1. p Lo s’ogba Getsemane,
Gbogbo eyin t’a ndan wo;
Wo iwaya ‘ja Jesu;
Ba sona wakati kan!
Ma keyin s’irora Re
Ko bi Krist’ ti ngbadura.

2. p Ba lo, si gbongan ‘dajo;


Wo b’Oluwa ti duro;
Ni ‘kedun ati ‘rora,
di A! ibanuje Re po!
Fi ara da idanwo,
Ko lati gb’agbelebu.

3. p Gori oke Kalfari


K’o si wole l’ese Re;
Kiyesi ‘se ‘yanu na;
di Olorun s’etu pari
“O pari” gbo igbe na;
pp Jeki Krist’ koo b’a ti ku.

4. mf Yara lo si iboji
Nibit’a gbe te E si;
p Wo bi ‘be ti pa roro,
Tani gb’Olugbala lo?
cr Krist’ ti jinde, a ti ri I:
f Jesu je k’a jinde be.
Amin.
297
L.M.
Nigbana ni Jesu ba won wa si ibikan ti a npe ni Getsemane. Mat. 26:36.

1. mpOganjo gan l’oke Olif’,


Awon irawo si ti wo:
Oganjo gan nisisiyi
p Krist’ nikan ngbadura l’ogba.

2. mpOganjo gan lai r’enikan,


Jesu nikan ba eru ja;
Omo-eyin t’O fe papa
Ko nani ibanuje Re.

3. mpL’oganjo f’ese elomi,


Eni kanu nsokun n’n’eje,
p Sibe, en’ t’o wole l’anu
Olorun ko je d’ehin ko.

4. mpOganjo gan; lati papa


f A ngb’orin awon angeli,
cr Orin titun t’a ko gbo ri
p L’o tu Olugbala l’ara
. Amin.
298
L.M.
O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, Ipinlese ati opin. Ifi. 21:6.

1. p “O pari” l’Olugbala ke,


pp O te ori ba, O si ku,
cr “O pari” Ire ije pin;
f O ti jagun! O si segun.

2. mf “O pari”! gbogb’ase orun


Ati asotele ‘gbani
L’a mu se b’a ti so tele
N’nu Krist’Olugbala aye.

3. mf “O pari” Igbe iku yi


Y’o s’etutu f’ese gbogbo,
Opo y’o si ri igbala
Nipa emi ‘kehin Jesu.

4. mf “O pari” k’iro ayo yi


Ka gbogbo orile-ede;
“O pari!” k’isegun na de,
K’o dapo mo orin t’oke
. Amin.
299
C.M.
Sa ro ti Eniti O farada iru isoro-odi yi lati odo awon elese si ara won. Heb. 12:3.

1. mpWo Olugbala araye


T’A kan m’agbelebu!
Ife na ti po to, t’O fe
Lati wa ku fun o!

2. p Gbo ‘kerora Re! Bo ti ke,


Isele nla-nla se;
cr Ikele tempili pin meji,
pp Okuta re si san.

3. mf O pari! A ti san ‘gbese,


di O ke, “gba emi MI”;
Wo b’O ti te ori Re ba,
pp O te ba O si ku.

4. cr Laipe, y’O ja ide iku


ogo Re y’o si tan;
f Olugbala, ko si ‘rora;
ff Tabi ‘fe bi Tire.
Amin.
300
8.7.8.7.D.
On o ru aisedede won wonni. Isa. 53:11.

1. mpW’Olori Alufa giga,


B’o ti gbe ebe wa lo;
p L’ogba O f’ikedun wole
O f’eru d’oju bole;
Angeli f’idamu duro
Lati ri Eleda be;
cr Awa o ha wa l’aigb’ogbe,
T’a mo pe ‘tori wa ni?

2. mf Kiki eje Jesu nikan


L’o le yi okan pada;
On lo le gba wa n’nu ebi,
On lole m’okan wa ro;
Ofin at’ikilo ko to,
Won ko si le nikan se;
cr Ero yi lo m’okan ro;
Oluwa ku dipo mi.

3. mf Jesu, gbogbo itunu wa,


Lat’odo Re lo ti nwa;
cr Ife, gbagbo, ‘reti, suru,
Gbogbo re l’eje Re ra;
f Lat’inu ekun Re l’a ngba,
A ko da ohun kan ni;
L’ofe n’Iwo nfi won tore
Fun awon t’o s’alaini.
Amin.
301
L.M
Emi nsokun nitori nkan wonyi; oju mi san omi sile. E.jer.1;16

1 mpAra,e wa ba mi s’ofo’
E wa s’odo Olugbala;
Wa, e je ka jumo s’ofo;
p A kan jesu m’agbelebu.

2 mpKo ha s’omije l’oju wa


Bi awon ju ti nfi s’efe?
A ! e wo, b’O teriba;,
p A kan jesu m’agbelebu.

3 m,pEmeje l’O s’oro ife,


p Idake wakati meta
L’o fi ntoro anu feyan
A kan jesu m’agbelebu

4 cr Bu sekun, okan lile mi,


mpEse at’igberaga re
L’o da Oluwa re l’ebi;
p A kan jesu m’agbelebu

5 Ibanuje at’omije
Ber a ki o fi du o;
‘Banuje t’Onf’ife Re han;
p A kan jesu m’agbelebu

6 cr Ife Baba ese eda


N’ihin l’a ri agbara Re
Ife ;’O si asegun,
p A kanOlufe wa mo’gi
. Amin
302
6.5.6.5.
Eje kristi iyebiye. 1 Pet 1:19

1 Ogo ni fun Jesu


p T’O fi riora nla
cr Ta eje Re fun mi
Lati iha Re.

2 f Mo r’iye ailopin
Ninu eje na;
Iyonu Re sa po,
Ore Re ki tan!

3 f Ope ni titi lae


F’eje ‘yebiye
T’O ra aye pada
.Kuro n’nu egbe

4 mf Eje Abel’ nkigbe


Si orun f’esan’
Sugbon eje Jesu nke
f Fun’dariji wa,

5. f Nigbat’aye ba nyo,
Abel’ nkigbe
Si orun f’esan;
Sugbon eje Jesu nke
f Fun ‘dariji wa.

6 p ngbe ‘yin Re ga;


Awon ogun angel’
A ma f’ayo gbe.

7. f Nje e gb’ohun yin ga,


Ki iro na dun!
ff Nigbati a bu won
Okan ese wa,
Satan, n’idamu re
F’eru sa jade. T’o Kikan l’ohun goro
Yin Od’agutan.
Amin.
303
C.M.
Nigbati won de ibi ti a npe ni Agbari, nibe ni nwon gbe kan A mo agbelebu. Llk.
23:33.

1. mf Oke kan mbe jina rere


L’eyin odi ilu;
p Ninit’a kan Oluwa mo
cr Eni t’o ku fun wa.

2. p A ko le mo, a ko le so
B’irora Re ti to
cr Sugbon a mo pe ‘tori wa
L’o se jiya nibe.

3. mf O ku k’a le ri ‘dariji,
K’a le huwa rere
cr K’a si le d’orun nikeyin
p Ni ‘toye eje Re.

4. mf Ko tun s’eni re miran mo


T’o le sanwo ese!
cr Oun l’o le silekun orun
K’o si gba wa sile.

5. f A! b’ife Re ti sowon to;


O ye ka feran Re;
K’a si gbekele eje Re
K’a si se ife Re
. Amin
304
C.M.
E duro nihinyi ki e si ma ba mi sona. Mat. 26:38.

1. p Okun l’ale tutu n’ile


Nibi Kristi wole;
p Ogun Re bi iro eje
Ninu ‘waya ija.

2. mf “Baba gb’ago kikoro yi


B’O ba se ife Re,
Bi beko, emi o si mu
Ife Re ni k’a se”.

3. Elese lo wo l’agbala
Eje mimo wonni;
p O r’eru ‘wuwo ni fun o
O si mu ‘po ‘rele.

4. Ko lati gbe agbelebu,


Se ife ti Baba;
Nigba idanwo sun mo le
ff Ji, sora, gbadura.
Amin.
305
C.M.
Alabapin ninu iya Re. Fili. 3:10.

1. p Ki Jesu ha nikan jiya,


K’araye lo l’ofo?
p Iya mbe f’olukuluku
cr Iya si mbe fun mi.

2. mf Ayo awon mimo tito


T’won banuje l’aye;
Nisiyi won ngbe ‘nu ife
f Ati ayo pipe.

3. p Em’o ru agbelebu mi
Tit’ iku y’o gba mi,
mf ‘Gbana un o lo ‘le lo d’ade
Tor’ade mbe fun mi.
Amin.
306
8.7.8.7.4.7.
O pari. Jn. 19:30.

1. mf E gb’ohun ife at’anu


Ti ndun l’oke Kalfari!
Wo! O san awon apata!
O mi ‘le, o m’orun su!
p “O ti pari”, “O ti pari”
Gbo b’Olugbala ti nke.

2. mp“O ti pari”, b’o ti dun to


Ohun t’oro wonyi wi,
Ibukun orun l’ainiye
Ti odo Krist’ san si wa;
“O ti pari”, “O ti pari”
p Ayanfe, ‘tunu l’eyi.

3. f Ise igbala wa pari,


Jesu ti mu ofin se!]
O pari nkan t’Olorun wi,
Awa ki o ka ‘ku si;
p “O ti pari”, “O ti pari”,
Ayanfe, ‘tunu l’eyi.

4. f E tun harpu yin se Seraf’


Lati korin ogo Re;
Araye at’ara orun
ff Yin oruko Imanuel’
p “O ti pari” “o ti pari”
Ogo fun Od’agutan.
Amin.
307
6.6.6.6.6.6.
O fi emi Re lele fun awon agutan Re. John 10:11

1. O f’ara Re fun mi,


p O ku nitori mi
cr K’o le ra mi pada,
Ki nle jinde n’noku,
O f’ara Re fun mi
p Ki l’emi se fun o.

2. O f’ojo aye Re,


Se wahala fun mi;
Ki emi ba le mo,
Adun ayeraye,
O l’opo odun fun mi
Mo lo kan fun o bi?

3. p O jiya po fun mi
Ti enu ko le so,
O jijakadi nla
cr ‘Tori igbala mi,
O jiya po fun mi
mpMo jiya fun o bi?

4. f O muigbala nla
Lat’ile Baba Re
Wa lati fi fun mi
O si dariji mi
O m’ebun wa fun mi
Kin’ mo mu wa fun o?

5. mf Un o f’ara mi fun o
Un o f’aye mi sin o
Un o diju si aye
Un o wo ohun t’orun
Mo f’ohun gbogbo mi
F’Oluwa Oba mi.
Amin
308
C.M.
Wo Odo-agutan Olorun. Jn. 1:36.

1. mf Wo Od’agutan ti o ru
Eru re lor’igi;
O ku lati da igbekun,
p O t’eje Re fun o.

2. mpW’Olugbala tit’iran na
Y’o fi fa okan re;
p Fi omije rin ese Re,
Ma kuro lodo Re.

3. cr Wo, tit’ife Re yio fi


Joba lor’okan re,
Tit’agbara Re y’o fi han
Lor’ara on emi.

4. mf Wo O bo ti nsare ije
Ore re titi lae;
f Y’o pari ise t’O bere,
Or’ofe y’o j’ogo.
Amin.
309
8.7.8.7.
Koju si Mi, ao si gba nyin la. Isa. 45:22.

1. mf Wakati didun ni fun mi


p Ni wiwo agbelebu;
cr Nibe, Jesu fun mi n’iye,
Ilera at’alafia.

2. mpNihin l’emi o gbe joko


Lati wo isun eje,
Eyiti y’o we okan mi
K’Olorun ba le gba mi.

3. mf Niwaju agbelebu Re,


L’emi ba buruburu
‘Gbat’emi ba ri ‘yonu nla
T’o farahan l’oju Re.

4. Ife ati omije mi


Ni un o fi we ese Re;
cr ‘Tori mo mo pe iku Re
Y’o mu iye wa fun mi.

5. mf Oluwa, jo gba ebe mi,


cr Se okan mi ni Tire,
f Tit’emi o fi r’igbala
At’oju Re nin’ogo.
Amin.
310
L.M.
Sugbon ki a mase ri pe, emi nsogo bikose ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa. Gal.
6:14.

1. mf ‘Gbati mo ri agbelebu
Ti a kan Oba Ogo mo
Mo ka gbogbo oro s’ofo
Mo kegan gbogbo ogo mi.

2. cr K’a mase gbo pe mo nhale


B’o ye n’iku Oluwa mi
Gbogbo nkan asan ti mo fe
Mo da sile fun eje Re.

3. p Wo, lat’ori, owo, ese


B’ikanu at’ife ti nsan;
cr ‘Banuje at’ife papo,
A f’egun se ade ogo.

4. mf Gbogbo aye ‘ba je t’emi;


Ebun abere ni fun mi;
f Ife nla ti nyanilenu
Gba gbogbo okan, emi mi
. Amin.
311
S.M.
O pari. Jn. 19:30.

1. mpIfe l’o to bayi!


Ohun gbogbo pari,
O ti pari gbogbo ise
T’O tori re w’aye.

2. Ohun ti Baba fe
Ni Jesu ti se tan;
p Wahala ati iya Re
cr Mu iwe mimo se.

3. Ko s’irora wa kan
Ti Jesu ko je ri;
Gbogbo edun at’aniyan
L’okan Re si ti mo.

4. L’ori t’a f’egun de,


At’okan Re mimo
L’a ko gbogbo ese wa le
cr K’O ba le wo wa san.

5. p Ife l’o mu k’O ku


Fun emi otosi,
cr ‘Wo etutu f’ese gbogbo
Mo f’igbagbo ro mo.

6. mf Nigba aini gbogbo,


Ati n’ite ‘dajo
cr Jesu, ododo Re nikan
Ni igbekele mi.

7. mf Jo, sise ninu mi,


Bi O ti se fun mi,
cr Si je ki ife mi si O
Ma fi ore Re han.
Amin.
312
5.5.11.D.
Ko ha kan nyin bi, gbogbo enyin ti nkoja? E. Jer. 1:12.

1. mf Eyin ti nkoja,
Ya s’odo Jesu;
mpO ha s’asan fun yin bi Jesu ba ku;
Olurapada,
Onigbowo yin,
p Wa, wo bi ‘banuje kan ri bi Tire.

2. cr Eje Re s’etu
Fun ese t’e da,
mpBaba se omo Re n’ise ntori yin,
Oluwa, ni ‘jo,
Ti ‘binu Re ru,
K’ese yin l’Od’agutan t’O ko won lo.

3. mf O duro fun wa,


E wa je ‘pe Re
E fi ‘yanu wole lab’agbelebu!
E gb’oju woke,
Bi Jesu ti nke,
p O jiya laibohun; Eni aiku ku.

4. mf O s’etu f’ese
Ti ki se Tire
O san igbese yin, O sise fun yin;
Gbogbo yin le pin
N’nu alafia Re,
mpEni bebe pe; “Baba mi dariji”

5. mf O bebe fun wa
Lor’agbelebu,
Adura Re gba, elese domnira;
Emi elese
T’o gba Jesu gbo,
Mo wa gba ‘fiji t’O ki o fi du mi.

6. mpMa toro ‘fiji;


Nitori mo je
Elese t’o gba oruko Jesu gbo
O ra or’ofe
Ti mo gba mora;
Baba, Iwo mo pe O ku dipo mi.

7. cr Iku Re setu;
‘Wo Alagbawi mi
Gbo b’eje t’a ta ‘le ti mbebe fun mi;
O ra mi pada,
‘Gba t’O ku lor’igi;
f Emi Re t’O fi lele da mi lare.
Amin.
313
C.M. & Ref.
Wo o, ki e si ri bi ibanuje kan ba wa. Bi ibanuje mi. E. Jer. 1:12.

1. mf Olugbala mi ha gb’ogbe!
Oba ogo ha ku!
On ha je f’ara Re rubo
F’eni ile b’emi.
Ran mi lowo Olugbala,
Lati fe O toto.
‘Gbat’O ba de ijoba Re
Oluwa ranti mi.

2. mpIha se ese ti mo da
L’o gbe ko s’or’igi?
Anu at’ore yi ma po
cr Ife yi rekoja!

3. mpO ye k’orun f’oju pamo,


K’o b’ogo re mole,
‘Gbati Kristi Eleda ku
Fun ese eda Re.

4. mpBe l’o ye k’oju ko ti mi


‘Gba mo r’agbelebu,
O ye k’okan mi kun f’ope
Oju mi f’omije.

5. mf Sugbon omije ko le san


‘Gbese ‘fe ti mo je;
Mo f’ara mi f’Oluwa mi
Eyi ni mo le se.
Amin.
314
7.7.7.6.
ORO MEJE KRISTI L’ORI AGBELEBU

BABA DARIJI WON NITORI TI NWON KO MO OHUN TI NWON NSE. Lk.


23:34.

1. mf ‘Wo t’O mbebe f’ota Re,


L’ori ‘gi agbelebu;
Wipe, “Fiji won, Baba”,
p Jesu, sanu fun wa.

2. mf Jesu jo bebe fun wa,


Fun ese wa ‘gba gbogbo
A ko mo ohun t’a se;
p Jesu, sanu fun wa.

3. mf Je k’awa ti nwa anu


Dabi Re l’okan n’iwa,
Gbat’a ba se wa n’ibi;
p Jesu, sanu fun wa.

LONI NI IWO O WA PELU MI NI PARADISE Lk. 23:43.

4. mf Jesu, ‘Wo t’O gbo aro


Ole t’o ku l’egbe Re,
T’O si mu d’orun rere
p Jesu, sanu fun wa.

5. mf Ninu ebi ese wa,


Je k’a toro anu Re;
K’a ma pe oruko Re,
p Jesu, sanu fun wa.

6. mp Ranti awa t’o nrahun,


T’a now agbelebu Re,
F’ireti mimo fun wa,
p Jesu, sanu fun wa.

OBIRIN, WO OMO RE: OMO WO IYA RE. Jn. 19:26&27

7. mf ‘Wo t’O fe l’a fe dopin


Iya Re t’o nkanu Re
Ati ore Re owon;
p Jesu, sanu fun wa.

8. mf Jeka pin n’nu iya Re,


Ka ma ko iku fun O,
cr Je k’a ri ‘toju Re gba;
cr Jesu, sanu fun wa.

9. f Ki gbogbo awa Tire


Je omo ile kanna;
cr Tori Re ka fe ‘ra wa;
p Jesu, sanu fun wa.

OLORUN MI, OLORUN MI, ESE TI IWO FI KO MI SILE? Mat. 27:46.

10. mf Jesu ‘Wo ti eru mba,


‘Gbat’O si ku ‘Wo nikan
cr Ti okunkun su bo O,
p Jesu, sanu fun wa.

11. mf ‘Gbati a ba npe lasan,


T’ireti wa si jina,
N’nu okun na di wa mu,
p Jesu, sanu fun wa.

12. mf B’o dabi Baba ko gbo,


B’o dabi ‘mole ko si,
Jeka f’igbagbo ri O,
p Jesu, sanu fun wa.

ORUNGBE NGBE MI. Jn. 19:28.

13. mf Jesu, ninu ongbe Re


Ni ori agbelebu,
cr ‘Wo ti O fe wa sibe,
p Jesu, sanu fun wa.

14. mf Ma k’ongbe fun wa sibe,


Sise mimo l’ara wa;
Te ife Re na l’orun;
p Jesu, sanu fun wa.

15. mf Jeka kongbe ife Re


Ma s’amona wa titi,
Sibi omi iye ni,
p Jesu, sanu fun wa.
O PARI. Jn. 19:30.
16. mf Jesu Olurapada,
‘Wo t’O se ‘fe Baba Re,
T’O si jiya tori wa
p Jesu, sanu fun wa.

17. mf Gba wa l’ojo idamu,


Se Oluranlowo wa,
Lati ma t’ona mimo,
p Jesu, sanu fun wa.

18. mf F’Imole Re s’ona wa


Ti yo ma tan titi lae,
Tit’ao fi de odo Re;
p Jesu, sanu fun wa.

BABA, LI OWO RE NI MO FI EMI MI LE. Lk. 23:46.

19. mf Jesu, gbogbo ise Re,


Gbogbo idamu Re pin,
f O jow’emi Re lowo,
p Jesu, sanu fun wa.

20. mp ‘Gba ti ‘ku ba de ba wa,


Gba wa lowo ota wa,
f Yo wa ni wakati na,
p Jesu, sanu fun wa.

21. Ki iku at’iye Re,


Mu ore-ofe ba wa,
Ti yio mu wa doke;
p Jesu, sanu fun wa.
Amin.
315
10.9.
ITAN ORI AGBELEBU
Nwon o ma wo eniti a gun li oko. Jn. 19:37.

GETSEMANE
1. p N’iwaya ‘jakadi, / On nikan nja,
O nfe iranlowo / sugbon ko ri.

2. B’osupa ti now / l’or’oke Olif’,


Adura tani ngoke / l’oru yi?

3. Eje wo l’eyi ti nro bi ojo,


Lat’okan Re wa, “Eni banuje”

4. Irora aileso / mbe l’oju Re,


Ojiya ti mbebe, tan’ Iwo?

ONA IKANU
1. mp Gbo b’O ti mba o so / ‘ro lokan re
“Omo ti mo kun fun / tele mi”

2. Ki nma m’ago ti /Baba fun mi bi


Gbati mimu re je / gbala re

3. A lu, a tuto si / a fi s’ efe;


A na, a si de/ l’ade egun.

4. Mo nlo si Golagota/ nibe Un o ku,


cr Tor’ ife Mi si O / Emi ni.

ORO MEJE LORI AGBELEBU

1. mp A kan mo ‘gi esin / ko ke rora,


Or’eru wa, / Tire ko.

2. Wo orun mi o le /wo okun bi?


Oro wo lo nte / nu Re wa ni

3. ‘Baba dariji won / l’adura Re


cr Baba si gbo , bi/ ti ma gbo ri,

4. Gbo bi ole ni ti / ntoro anu;


mf On se leri pa/ radise fun.
5. Ibatan at’ ore/ rogba yika ,
Maria on Magdalen ropin re.

6. Meji ninu won di / tiyat’ omo ,


Okan t/oro Re / ti sod’okan.

7. p Okunkun bo ile/ osan d’oru,


Iseju koja b’/odun pipo.

8. pp Gbo’ gbe’ rora lat’ i/nu okun na


‘Baba, Wo ko mi /sile ese?

9. A ikosile nla /iku egun;


Igbe kil eyi / Ongbe Mi’

10. cr Gbo, O ti pari ‘/ Ijakada pin,


Iku at’ ipoku /a se won.

11. p ‘Baba, gba emi mi ‘/ L’o wi keyin.


Krist’ Oluwa iye / O si ku.

IKESI

1. mp ‘ O mo’ rora mi ti / mo d’ eje ra ,


Mo gba o low’ esu f’ Olorun;

2. cr “Wa alare, wa f’ori / laya mi,


Sapamo sodo mi, / ko simi.

3. mf “Wa sodo Baba mi, / wa laiberu,


Alagbawi re, / wa nitosi.

4. “Wa mu ninu ore / ofe emi;


Emi ni ini re / ‘Wo t’emi.

IDAHUN
1. mf Mo fara mi fun O / Oluwa mi,
Sa fi ‘fe Re ‘yebiye fun mi.

2. mf Gbogb’ohun ti mo ni / t’ara t’okan


Nko je fi du O / gba gbogbo re.

3. cr Sa ba mi gbe dopin / Oluwa mi,


Jesu, Olugbala / Oluwa mi.
4. B’akoko Re ba de / je ki nyin O
Yin O nile Re / titi laelae.
Amin.
316
C.M. & Ref.
On si ti fi eje agbelebu Re se ilaja. Kol. 1:20.

1. mp O se! Olugbala mi ta
p ‘Je Re sile, O ku,
Nje O je fori mimo na
Fun kokoro b’emi.
mf Nibi agbelebu ni mo ko ri ‘mole
Nibe, eru okan mi si fo lo;
Nibe, nipa igbagbo, mo riran,
f N’siyi, mo wa l’alafia titi.

2. mp Nje ‘tor’ese ti mo ti da
L’O se jiya oro,
Anu at’ore ofe yi
Ko se diwon rara.

3. p O to k’orun ko s’okunkun,
Ko f’ogo re pamo;
Nigba Kristi Eleda nla ku
Fese awa eda.

4. cr Sugbon ‘banuje ko le san


‘Gbese ‘fe ti mo je,
mf Kristi mo f’ara mi fun O
Eyi ni mo le se.
Amin.
317
7.7.7.8.
A kegan Re, a si koo lodo awon eniyan. Isa. 53:3.

1. p Eni ‘kanu! – oruko


cr T’a npe Omo Olorun;
f T’O wa gba elese la!
ff Aleluya! Olugbala!

2. mf O farada eleya,
A da lebi nipo mi!
Eje Re setu fun mi
ff Aleluya! Olugbala!

3. cr Otos’elese ni wa;
Alailabawon li On:
Nje loto l’O setutu?
ff Aleluya! Olugbala!

4. mp A gbe ko sori igi,


p O ke pe, O ti pari!
A gbe ga lorun n’isiyi:
Aleluya! Olugbala!

5. mf ‘Gbat’Oba Ogo ba de,


‘Lati m’eni Re re ‘le
Ao ko orin yi lotun
ff Aleluya! Olugbala!
Amin
318
8.8.8.8.8.8.
Nigbati awa je elese, Kristi ku fun wa. Rom. 5:8.

1. mf O ha le je pe mo n’ipin
Ninu eje Olugbala?
P’O ku f’emi t’O da loro,
T’o lepa Re doju iku?
f Ife ‘yanu! e ha ti se
Ti ‘Wo Olorun ku fun mi?

2. p Ohun ‘jinle! Olorun ku!


Tani mo idi ete Re?
Lasan l’angeli ta ko da
Nfe mo, ‘jinle ife mimo!
Anu sa ni! k’aye juba,
Ki angeli ma wadi mo.

3. mf O f’ite Baba Re sile,


Ore-ofe Re ko lopin!
O bo gbogb’ogo Re sile,
O ku fun ‘ran omo Adam,
Anu sa ni, laini iwon;
f L’O wa mi ri, Olorun mi.

4. mf O pe ta ti de emi mi
Sinsin l’o kun ewon ese;
Oju Re tan ‘mole iye,
Mo taji, tubu si mole;
Ewon mi bo, mo d’ominira
Mo dide, mo si nto leyin.

5. p Emi ko jaya ebi mo;


Temi ni Krist, patapata!
mf Mo ye ninu Olori mi,
A f’ododo orun wo mi,
N’igboya, mo sunmo ite,
Mo gba ade, lagbara Kristi. Amin.
319
L.M.
Kristi Jesu, eniti Olorun fi se ogbon ati ododo, ati isodimimo ati idande fun wa. I Kor.
1:30.

1. mf Jesu, eje ododo Re


Li ewa ati aso mi;
Bi mba wo won, b’aye ngbina
f Un o f’ayo gb’ori mi soke.

2. f Un o ni ‘gboya l’ojo ‘dajo;


Tani ‘ba ka si mi lorun?
A we mi mo patapata
Kuro l’ese, l’eru, l’ebi.

3. mpAlailegan Od’agutan
T’O t’okan-aya Baba wa,
T’O ku lati setu fun mi,
Ni mo yan ni Olorun mi.

4. mpOluwa, emi gbagbo pe


Eje Re nib’ite-anu
Ti nsipe lae fun elese
p L’a ta sile fun emi mi.

5. mf Oluwa, mo si gbagbo pe
B’elese po bi iyanrin,
‘Wo ti ra gbogbo won pada,
cr ‘Wo ti setu fun gbogbo won.

6. mf ‘Gba mba jinde ninu oku


Lati gba ‘bugbe mi lorun,
Eyi ni yo je ebe mi,
p Jesu w’aye, O ku fun mi.
Amin.
320
9.9.9.9. & Ref.
Nigbati emi ba ri eje na, emi o re nyin koja. Eks. 12:13.

1. p Kristi ku l’ori agbelebu,


O ku fun igbese elese,
F’e j’Odagutan we okan re,
On yoo si re yin koja lo.
mp ‘Gba to ba ri eje
‘Gba to ba ri eje
‘Gba to ba ri eje
On yio re yin koja lo.

2. mf Jesu y’O gbeni to buru ju,


Yio mu gbogbo ileri se,
We n’nu orisun iwenumo,
On yoo si re yin koja lo.

3. mp Idajo mbo fun gbogbo aye,


Olukuluku y’o gba ere,
F’eje ‘wenumo se abo re,
On yoo si re yin koja lo.

4. mf A! anu at’ife ailopin,


A! inu rere at’otito,
Wa alafia n’nu eje na,
On yoo si re yin koja lo.
Amin.
321
11.11.11.7.7. & Ref.
Li ojo ti mo kepe, iwo da mi lohun, Iwo si fi ipa mu mi lara le li okan. OD.
138:3.

1. mf Mo nko ‘rin ti Eni t’o gb’emi mi la,


Mo rom’Ore na to so mi di pipe,
Ni ‘daniloju pe nigba mba dele
Lojukoju ni un o ri.
f Lojukoju ni un o ri
Mo gbekel’or’ofe Re,
Nipari ‘rin ajo mi,
Lojukoju ni un o ri.

2. cr Mo ngbe ‘nu Eni Kanna ti mo njuba


Lojojo ni mo si nrohin ore Re,
Pe lehin gbogbo idanwo aye yi,
Lojukoju ni un o ri.

3. mf Mo ngbe ninu ‘mole orun ife Re,


Mo si nka fun ojo ‘kore ti oke,
Ti mo ba si je olotito nihin,
Lojukoju ni un o ri.

4. f Niwaju Re, mo nri alafia pipe,


Itan Re mu ‘nu gbogbo eniyan dun,
Ni ‘daniloju pe nile wa loke
Lojukoju ni un o ri.
Amin.
322
8.8.8.6.D.
Olufe mi ni temi, emi si ni Tire. O. Sol. 2:16.

1. mf Ife ti Jesu ni si mi,


To jiya lor’agbelebu,
Ki mba le d’eni rapada
Ju ‘yi t’ahon le so.
ff Ife Re si mi po jojo
Ju ‘yi ti mo le rohin lo,
Ife ti Jesu ni si mi
Ju ‘yi t’ahon le so.

2. p Iya kikoro ti o je
At’ade egun t’a fi de
Ki mba le ye titi aye
Ju ‘yi t’ahon le so.

3. mf Ibale okan t’O nfun mi,


Ebe t’O mbe fun mi loke,
Ore t’eje Re nse fun mi
Ju ‘yi t’ahon le so.

4. f Ayo ti mo ni ninu mi,


Isimi at’alafia;
Ireti pe O tun mbo wa
Ju ‘yi t’ahon le so.
Amin.
323
O si se alafia nipa eje agbelebu Re. Kol.1:20

1. mf Agbelebu ni ere mi,


Nibe nia rubo fun mi.;
Nibe l’a kan Oluwa mo;
Nibe l’Olugbala mi ku.

2. mf Kini o le fa okan Re.


Lati teri gba iya mi?
Ajmohun na daju l’o se
p T’okan mi tutu be si O.

3. mf Aifohun na oju ti mi
Niwaju Jesu mimo mi,
p T’O taje Re sile fun mi,
Tori o fe mi l’afeju.
Amin.
324
C.M.
Awon wonyi ni nto Odo-agutan lehin, nibikibi ti nre.Ifi. 14:4.

1. mf Eje k’a to Jesu wa lo,


Ni agbala nla ni;
Nibiti o nlo gbadura,
p Nibit’o nlo kanu.

2. K’a wo b’O ti dojubole,


p T’O nmi imi edun;
Eru ese wa l’O gberu,
Ese gbogbo aye.

3. Elese, wo Oluwa re,


Eni mimo julo;
Nitori re ni Baba ko O,
Aye si d’ota Re.

4. mf Iwo o ha wo laironu,
;ai k’ese re sile?
p Ojo idariji nkoja,
Ojo igbala nlo.
Amin.
325
6.6.6.6.8.8.
Ko si nihin yi, sugbon O jinde. Lk. 24:6.

1. mf Pelu iye didan


L’oro kutukutu,
L’angeli sokale,
cr O y’okuta kuro.
f E jumo gb’ohun yin soke,
Eyin Oluwa t’O jinde.

2. mf ‘Gbat’awon oluso
Ri iran eru na
Won subu lojiji,
Won si dabi oku.

3. cr O nde n’isa oku,


Oju eda ko ri;
O segun iboji,
Oluwa gbogb’aye.

4. cr Eyin omo ‘mole,


E nde pel’Oluwa;
Wo bi irawo Re,
Ti ntan l’oju orun.

5. mpFi ohun atijo


Sile ninu ‘boji,
A sin yin n’nu Jesu,
E ba jinde loni.

6. A yin O Oluwa,
Pelu agbara wa
N’tori a je Tire,
‘Wo si je tiwa lae.
Amin.
326
S.M.
Nwipe, Oluwa jinde, nitoto O si ti fi ara han fun Simoni. Lk. 24:34.

1. f Oluwa ji loto,
Ise ‘gbala pari,
A tu awon onde sile,
A si s’ete iku.

2. f “Oluwa ji loto”
Esu so tire nu,
Awon t’ara ji pelu Re
Lati joba laelae.

3. f “Oluwa ji loto”
O mbe, ko ni ku mo,
O mbe, lati be f’elese
Ti O ru egun won.

4. f “Oluwa ji loto”
Eyin Angeli gbo,
S’agbala orun, e sare,
Mu ‘hin ayo na lo.

5. ff E mu dru wura
K’e si te ‘rin didun!
Eyin egbe orun dapo
Lati k’ajinde Re.
Amin.
327
8.7.8.3.
Aworan re yio te mi lorun nigba ti mo ba ji. O.D17:15.

1. f L’owuro ojo ajinde


T’ara t’okan yo pade
Ekun, kanu on irora
Yo dopin.

2. p Nihin, won ko le sai pinya


Ki ara ba le simi
Ko si fi idake roro
Sun fonfon.

3. Fun ‘gba die ara are yi


La gbe sibi ‘simi re
cr Titi di imole oro
Ajinde.
4. mf Sugbon okan to ns’asaro
To si ngbadura kikan
f Yo bu s’orin ayo lojo
Ajinde.

5. mf Ara at’okan yo dapo


Ipinya ko ni si mo
cr Won o ji ‘aworan Krist’ni
‘Telorun.

6. f A! ewa na at’ayo na
Yo ti po to l’Ajinde!
Yo duro borun ataye
Ba fo lo.

7. mf L’oro ojo ajinde wa


‘Boji yo m’oku re wa
Baba, iya, omo , ara
Yo pade.

8. Si ‘dapo ti o dun bayi


di Jesu ma sai ka wa ye
p N’nu ‘ku ‘dajo, ka le ro m’a
Gbelebu.
Amin
328
6.6.6.6.8.8.
Iwo ti di igbekun ni igbekun lo. OD. 68:18.

1. f Oro ayo na de,


Olugbala bori;
cr O fi ‘boji sile
Bi Olodumare,
ff A d’igbekun ni ‘gbekun lo,
Jesu t’O ku di alaye.

2. p Onigbowo wa ku,
mf Tani to fi wa sun?
Baba da wa lare,
Tal’o to da ebi?

3. mf Kristi ti san gbese,


Ise ogo pari;
O ti ran wa lowo,
O ti ba wa segun.
Amin.
329
7.8.7.8.4.
Kiyesi i, Emi mbe laye titi lae Amin. Ifi. 1:18.

1. f Jesu ye titi aye,


Eru iku ko ba mi mo;
Jesu ye; nitorina
Isa oku ko n’ipa mo – Aleluya.

2. mf Jesu ye, lat’oni lo,


Iku je ona s iye;
Eyi y’o je ‘tunu wa
‘Gbat’akoko iku ba de – Aleluya.

3. mp Jesu ye; fun wa lo ku,


Nje Tire, ni a o ma se;
cr A o f’okan funfunsin,
A o f’ogo f’Olugbala – Aleluya.

4. f Jesu ye; eyi daju,


Iku at’ipa okunkun
Ki yo le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu – Aleluya.

5. Jesu ye; gbogbo ‘joba


L’orun, li aye, di Tire;
mf E je ki a ma tele,
cr Ki a le jona pelu Re – Aleluya.
Amin.
330
7.6.7.6.D.
Wo o, Jesu pade won, O wipe Alafia. Mat. 28:9.

1. f Eyi l’ojo ajinde,


Wi kakiri aye;
Irekoja didun ni,
T’Olorun Olore;
Lat’inu iku s’iye,
Lat’aye si orun,
ff Ni Krist’ ti mu wa koja,
Pel’ orin isegun.

2. mf Oluwa we okan wa,


Ko ba le mo toto;
Ka ba le ri Oluwa
N’nu ‘mole ajinde;
cr Ka si feti sohun Re
Ti ndun lohun jeje,
Pe “Alafia fun yin”
Ka nde, ka si tele.

3. f Eyin orun, bu sayo


K’aye bere gberin;
Ki gbogbo aye yika
Dapo lati gberin;
Eda nla ati wewe,
E gbohun yin soke
ff ‘Tori Kristi ti jinde,
Ayo wa ki yo pin.
Amin.
331
11.11.11.11.& Ref.
Mo si ni kokoro iku ati ti ipo oku. Ifi. 1:18.

1. f Kabo ojo rere l’ao ma wi titi;


Asete ku loni orun di tiwa,
‘Wo oku d’alaye, Oba tit’aye,
Gbogb’eda Re, Jesu, ni nwon njuba Re.
ff “Kabo ojo rere l’ao ma wi titi
Asete ku loni orun di tiwa,

2. mf Eleda, Oluwa, Emi alaye!


Lat’orun l’O ti b’ojuwo ‘sina wa;
Om’Olorun papa ni ‘Wo tile se,
K’O ba le gba wa la; O di eniyan.

3. mf ‘Wo Oluwa iye, O wa to ‘ku wo;


Lati f’ipa Re han, O sun n’iboji;
Wa, Eni Oloto, si m’oro Re se,
Ojo keta Re de, jinde Oluwa!

4. mf Tu igbekun sile, t’esu de l’ewon,


Awon to si subu, jo gbe won dide
F’oju rere Re han, je k’aye riran,
Tun mu mole wa de, ‘Wo sa ni ‘Mole.
Amin.
332
D.C.M.
Jiohun elo orin mimo ati duru emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD. 108:2.

1. f Ji, ji okan ayo ji, ji


Oluwa re jinde
Lo ‘boji Re, ko si mura
Okan ati korin;
Gbogbo eda lo si ti ji,
Ti won nkorin didun,
Itanna ‘kini to ko tan
Leba odo lo hu.

2. mf Isudede aye yo lo
Lojo ajinde yi;
Iku ko si mo ninu Kristi
Iboji ko n’ipa
f Ninu Kristi la nwa, ta nsun,
T’a nji, ta si ndide;
p Omije t’iku mu ba wa
cr Ni Jesu yo nu nu.

3. f Ki gbogbo eye at’igi


At’itanna ti ntan,
Ki won so ti isegun Re
Ati t’ajinde Re,
Papa, e gb’ohun yin soke
E bu sorin ayo,
Eyin oke, e si gberin
Wipe, “Iku ti ku”.

4. ff Okan ayo, e ji, e wa


Oluwa t’O jinde
E yo ninu ajinde Re,
K’oro Re tu yin n’nu;
E gb’ohun yin soke, k’eyin
Eni t’O ji dide;
L’ohun kan ni ka gberin pe,
Esu jinde fun mi”.
Amin.
333
8.8.8.4.
E korin titun si Oluwa, nitoriti ti o se ohun iyanu. OD. 98:1

ff ALLELUYA! ALLELUYA! ALLELUYA!,

1. f Ija d’opin, ogun si tan;


Olugbala jagun molu,
ff Orin ayo la o ma ko Alleluya.

2. f Gbogbo ipa n’iku ti lo,


Sugbon Kristi f’ogun re ka:
ff Aye! e ho iho ayo - alleluya

3. mf Ojo meta na ti koja,


cr O jinde kuro nin’oku,
ff E f’ogo fun Oluwa wa - Alleluya.

4. f O d’ewon orun apadi,


O silekun orun sile,
ff E korin iyin ‘segun Re- Alleluya.

5. p Jesu nipa iya t’o je,


mf Gba wa lowo oro iku,
cr K’a le ye, k’a si ma yin O-Alleluya.
Amin
334
7.7.7.7.& Aleluya
Kristi ti jinde. Mk. 16:6.

1. f Kristi’ Oluwa ji loni: Aleluya


Eda at’ Angeli nwi: Aleluya
cr Gb’ayo at’isegun ga Aleluya
ff Korun at’aye gberin Aleluya

2. mf Ise ti idande tan: Aleluya


O jija, O ti segun Aleluya
Wo sisu orun koja: Aleluya
Ko wo sinu eje mo Aleluya

3. mf Lasan n’iso at’ami, Aleluya


f Krist’ wo orun apadi Aleluya
Lasan l’agbara iku Aleluya
Kristi si Paradise Aleluya

4. f O tun wa, Oba Ogo: Aleluya


f “Iku itani re da: Aleluya
p L’ekan lo’ku, k’O gba wa: Aleluya
“Boji isegun re da? Aleluya

5. f E je kawa goke lo Aleluya


Sodo Kristi, Ori wa Aleluya
A sa jinde pelu Re: Aleluya
cr Bi a ti ku pelu Re: Aleluya

6. ff Oluwa t’aye t’orun Aleluya


Tire ni gbogbo iyin Aleluya
A wole niwaju Re Aleluya
‘Wo ajinde at’ iye, Aleluya
Amin.
335
8.7.8.7.D.
Eniti O tun wa bi sinu ireti aye nipa ajinde Jesu. I Pet. 1:3.

1. f Aleluya, Aleluya,
Egbe ohun ayo ga,
E ko orin inu didun
K’e si yin Olorun wa;
p Eni t’a kan m’agbelebu
T’O jiya fun ese wa,
ff Jesu, Kristi, Oba Ogo
Jinde kuro n’nu oku.

2. f Irin idabu se kuro,


Kristi ku, O si tun ye;
O mu iye ati aiku
Wa loro Ajinde Re;
Krist’ ti segun, awa segun
Nipa agbara nla Re
ff Awa o jinde pelu Re
A o ba wo ‘nu ogo.

3. mf Kristi jinde, akobi ni


Ninu awon t’o ti sun;
Awon yi ni y’o ji dide
Ni abo Re ekeji;
Ikore ti won ti pon tan,
Won nreti Olukore,
Eni ti y’o mu won kuro
Ninu isa oku won.

4. mf Awa jinde pelu Kristi,


T’O fun wa l’ohun gbogbo,
Ojo, iri, ati ogo
T’o ntan jade l’oju Re;
Oluwa ba ti wa l’aye,
Fa okan wa s’odo Re,
cr K’awon angeli sa wa jo
Ki won ko wa d’odo Re.

5. ff Aleluya, Aleluya,
Ogo ni fun Olorun;
Aleluya f’Olugbala
Enit’ t’O segun iku;
Aleluya, f’Emi Mimo
Orisun ‘fe wa mimo;
Aleluya, Aleluya
F’Olorun Metalokan. Amin.
336
L.M.
Emi li Eniti O mbe laye ti o si ti ku; si kiyesi i, Emi si mbe laye titi lae – Amin. Ifi.
1:18.

1. p Jesu, Ore elese ku,


Awon omo Salem nsokun,
Okunkun bo oju orun,
Isele nla se lojiji.

2. p Eyin Mimo, e wa sokun,


Eni t’O jiya n’tori yin;
pp On sokun kikoro fun yin
O ta ‘je Re owon fun yin.

3. mp Ife at’edun yi l’eke;


Oba ogo ku fun eda;
Wo ayo airotele de;
Jesu t’O ku, si tun jinde!

4. cr Olorun ko ‘boji sile,


‘Boji ko le da ‘jinde ro!
Ogun angel sin lo s’ile;
Won f’ayo gba soke orun.

5. f Ma sokun mo, eyin mimo,


E so p’Olugbala joba,
E korin ti isegun Re
f L’ori esu ati iku.

6. f E wipe, “Oba pe titi”,


Iwo ta bi lati gba wa,
E bi ‘ku pe “Oro re da”?
“Iboji, isegun re da”
Amin.
337
C.M.
Nigbati Jesu Gbo, O da li ohun pe: Ma beru. Lk. 8:50.

1. mf Eyin ti e nwa Oluwa


Ma jek’eru ba yin;
E f’ayo bojuwo ibi
Ta ti te Jesu si.

2. cr Oluwa Iye di oku,


Ise ife l’eyi;
Idake iku gba l’aya
To fi gbogbe fun O.

3. f Gb’oju soke, korin iyin;


Olugbala tun ye;
Gbogbo agbaa ‘ku ko to
Da Asegun duro.

4. mf Ga ju gbogbo angeli lo
L’O gb’ori Re soke;
Eni t’O gbe aarin oku,
Joba ayeraye.

5. f Awon mimo yo ji dide]


Pel’ ayo bi Tire!;
Won o si b’Oluwa goke
Lo s’aye ailopin.
Amin.
338
10.11.11.11. & Ref.
Ko a ye ki Kristi ki o jiya nkan wonyi ko o si wo inu ogo Re lo? Luk. 24:26

1. mf Tire ni ogo Omo nla Baba,


Titi ni ‘segun na t’O ni lori ‘ku
Awon angeli to y’okuta na kuro
F’aso ogbo na lele niboji Re.
f Tire ni ogo Omo nla Baba
Titi ni’segun na t’Oni lori ‘ku.

2. f Wo! Jesu ji dide ninu oku


O si fi ‘fe tu eru okan wa ka,
K’ijo Olorun f’ayo korin ‘segun,
Oluwa mbe, iku so oro re nu.

3. mf Aigba O gbo bila, Kristi Jesu


Laisi Re ko s’iye ran aini wa lowo
Mu wa, j’asegun lo nipa ife Re,
Tit’ao koja Jordan sile wa orun.
Amin
339
10.10.10.10.& Ref.
Tali Oba ogo yi? Oluwa awon omo ogun; On na li Oba ogo. OD. 24:10.

1. f Ke kabiyesi! gbe ilekun soke;


Lenu ona re Oba Ogo nduro!
Si okan re, si le ese jade,
Dide jeki Oba Ogo wole.
ff Tali On? Tal’Oba Ogo yi?
Jesu Oluwa li ola ye fun
Ke Kabiyesi! wole n’waju Re
Se l’Oba, l’Oba Oba gbogb’eda.

2. mf Lati agbala orun lojo na,


O sokale ni ara erupe;
Fun wa n’ijiya, ibanuje Re,
Ise irora ati ekun Re.

3. mp A kan mo ‘gi ika ati ‘tiju


F’eje Re ta ta ‘le lo se w’aye;
Gbo lat’enu Re igbe irora,
Nitori wa l’Olugbala se ku.

4. f Iku ko le bori Re niboji,


Lowuro lo jade kuro nibe,
O ji dide, o njoba ni oke,
Ki gbogb’aye f’iyin fun Oluwa.
Amin.
340
K. 170: t.H.C.245 S.M.
O jinde nitori idalare wa. Rom. 4:25.

1. f A mu ileri se
Ise ‘gbala pari;
Oto at’anu di ore
Om’Olorun jinde.

2. f Okan mi, yin Jesu,


T’oru gbogb’ese re,
p T’o ku f’ese gbogbo aye,
cr O wa k’o ma ku mo.

3. mp Iku Re re ‘simi,
Fun o l’O jinde
ff Gbagbo, gba ekun ‘dariji,
T’a sa l’ami eje.
Amin.
341
7.7.7.7.
O si wi fun awon omo-ehin pe, on ti ri Oluwa. Jn. 20:18.

1. f Orun, korin! Aye, yo


Angeli at’eniyan
Eyi ka b’O ti ndide,
E gbe ‘yin Jesu yin ga.

2. f A ti fo ejo l’ori,
A segun ‘ku at’Esu,
Labe Jesu t’O goke,
A ti mu ‘gbekun l’eru.

3. f Ise at’ija Re tan,


O lo sinu ayo Re,
O si mbe f’awon Tire,
Nibi ite Baba Re.
Amin.
342
C.M.
E yara lo so fun awon omo ehin Re pe, O jinde. Mat. 28:7.

1. mf Mo wi fun olukuluku
f Pe, On ji, O si ye;
O si wa larin wa pelu,
Nipa Emi iye.

2. E wi fun enikeji yin,


Ki won ji pelu wa,
K’imole k’o wa kakiri
Ni gbogbo aye wa.

3. Nisisiyi aye yi ri
Bi ile Baba wa:
Iye titun ti On fun ni,
O so d’ile Baba.

4. mf Ona okun ti On ti rin


Mu ni lo si orun;
Eni t’o rin bi On ti rin,
Y’o d’odo Re l’orun.

5. f On ye, O si wa pelu wa,


Ni gbogbo aye yi;
Ati nigbat’a f’ara wa,
F’erupe ni ‘reti.
Amin.
343
6.6.6.6.8.8.
Awon oba aye kese jo, ati awon ijoye ngbimo po si Oluwa. OD. 2:2

1. ff B’elese s’owo po,


Ti won nde s’Oluwa,
Dimo si Kristi Re,
Lati gan Oba na,
B’aye sata,
Pelu Esu,
Eke ni won,
Won nse lasan.

2. f Olugbala joba!
Lori oke Sioni;
Ase ti Oluwa,
ff Gbe Omo Tire ro;
Lati boji
O ni k’O nde,
K’O si goke,
K’O gba ni la.

3. mf F’eru sin Oluwa,


Si bowo f’ase Re;
F’ayo wa sodo Re,
F’iwariri duro;
p E kunle fun Un
K’e teriba;
So t’ipa Re,
Ki Omo na!
Amin.
344
C.M.
Wo ti di igbekin ni igbekun lo. OD. 68:18.

1. mf Jesu t’O ku, k’O gb’aye la,


Jinde kuro ninu oku,
Nipa agbara Re;
ff A da sile lowo iku,
O d’igbekun n’igbekun lo,
cr O ye, k’O ma ku mo.

2. Eyin om’Olorun, e wo
Olugbala ninu ogo;
O ti segun iku:
Ma banuje, ma beru mo,
O nlo pese aye fun yin,
Yio mu yin lo ‘le.

3. mf O f’oju anu at’ife


Wo awon ti O ra pada;
Awon ni ayo Re;
O ri ayo at’ise won,
O bebe ki won le segun,
ff Ki won ba joba lae.
Amin.
345
S.M.
Kristi ti jinde kuro ninu oku. I Kor. 15:20.

1. f “Oluwa ji loto”
Ihin na ha s’oto?
p Won ti ri p’Olugbala ku,
cr Won ri l’aye pelu.

2. f “Oluwa ji loto”
Oto ko fe ju yi;
Anu at’otito pade,
Ti won ti ns’ota ri.

3. “Oluwa ji loto”
Ise Re l’o setan;
f A da ide onigbowo,
A se apa iku.

4. “Oluwa ji loto”
mf Boji ko le se mo;
Awon t’o ku si ji pelu,
cr Won ki o si ku mo.
Amin.
346
6s. 8s.
Nigbati nwon wo inu boji, nwon ko si ba oku Jesu Oluwa. LK. 24:3.

1. Oluwa ji loto
Olugbala dide,
O f’agbara Re han;
L’or’orun apadi:
N’iberu nla: awon eso
Subu lule won si daku.

2. Wo, egbe Angeli


Pade l’ajo kikun:
Lati gbo ase, Re
Ati lati juba;
Won f’ayo wa, won si nfo lo,
Lati orun s’iboji na.

3. Won tun fo lo s’orun


Won mu ‘hin ayo lo;
Gbo iro orin won,
Bi won si ti nfo lo
Orin won ni Jesu to ku
Ti ji dide,; O ji loni.

4. Eyin t’ara pada


Egberin ayo na:
Ran iro re kiri
Si gbogbo agbaye
E ho f’ayo Jesu t’O ku
Ti ji dide: ki y’o ku mo.

5. Kabiyesi! Jesu!
T’O f’eje Re gba wa
Ki iyin Re kale
Iwo t’O ji dide
A ba O ji a si joba,
Pelu Re lai; loke orun.
Amin.
347
8.7.8.7.D.
Emi o si se awon ati ibiti o yi oke mi ka ni ibukun. Esek. 34:26.

1. mf Olorun wa mbe larin wa,


L’ati bukun gbogbo wa,
Wo oju orun b’o ti su
Yo ro ojo ibukun;
f K’o de Oluwa, a be O,
Je k’ojo ibukun de;
Awa nduro, awa nduro,
M’okan gbogbo wa soji.

2. mf Olorun wa mbe larin wa


Ninu ile mimo yi,
Sugbon a nfe ‘tura okan wa
At’opo or’ofe Re.

3. Olorun wa mbe larin wa,


K’a mu ebe wa t’O wa,
Ki ife Re ba le gberan
Lati m’okan wa gbona.

4. Jesu fi ‘bere wa fun wa,


B’a ti f’igbagbo kunle,
di Jo si ferese anu Re
K’o tu ‘bukun sori wa.
Amin.
348
S.M.
Ojo kan ninu agbala Re san ju egberun ojo lo. OD. 84:10.

1. mf Kabo! Ojo ‘simi


T’or’Oluwa jinde;
Ma bo wa s’okan ti nsoji,
At’oju ti nyo yi!

2. Oba Tika Re wa
Bo eni Re loni,
Nihin l’a le joko, k’a ri,
K’a fe, k’a yin, k’a sin.

3. Ojo kan nibiti


‘Wo, Oluwa mi ngbe;
O san j’egberun ojo lo
T’a nje faji ese.

4. f Okan mi yo f’ayo
Wa n’iru ipo yi,
Y’o joko, y’o ma korin lo
Tit’aye ailopin.
Amin.
349
7.7.7.7.D.
Ago Re wonni ti lewa to? OD. 84:1.

1. f ‘Bugbe re ti l’ewa to
N’ile ‘mole at’ife
‘Bugbe Re ti l’ewa to
L’aye ese at’osi!
Okan mi nfa ni toto
Fun idapo eeyan Re
Fun imole oju re
Fun ekun Re Olorun.

2. f Ayo ba awon eye


Ti nfo yi pepe Re ka,
Ayo okan t’o nsimi
L’aya Baba l’o poju
Gege b’adaba Noa
Ti ko r’ibi simi le
Won pada s’odo Baba
Won si nyo titi aye.

3. f Won ko simi iyin won


Ninu aye osi yi
Omi sun ni aginju
Manna nt’orun wa fun won
Won nlo lat’ipa de’pa
Titi won fi yo si o
Won si wole l’ese Re,
T’o mu won la ewu ja.

4. mf Baba, je ki njere be;


cr S’amona mi l’aye yi;
F’ore-ofe pa mi mo;
Fun mi l’aye l’odo Re
Iwo l’orun, at’a sa
To okan isina mi,
Iwo l’orisun ore,
Ro ojo Re s’ori mi.
Amin.
350
L.M.& Ref.
Gba mi nisisiyi, mo be O Oluwa. OD. 118:25

1. f Hosana si Oluwa wa
Hosana si Jesu Oba!
Si Eleda Olugbala
K’aye, k’orun ko Hosana,
Ko Hosana, “Hosana loke orun”

2. f Hosana l’orin angeli


Hosana l’orin ti a gbe
L’oke, nisale, yi wa ka,
Oku at’aye ngbe ‘rin na
ff Ko Hosana, “Hosana loke orun”

3. mf Olugbala ti ntoju wa
Pada wa ‘le adura yi,
Apejo ni oruko Re,
Mu ileri Re se si wa
cr Ko Hosana, “Hosana loke orun”

4. mf Sugbon bori ohun gbogbo


Fi Emi Re kun okan wa:
Ki okan wa je ibugbe
Mimo ati yiye fun O;
cr Ko Hosana, “Hosana loke orun”

5. p L’ojo ‘kehin ojo eru


T’aye on orun o koja;
cr Awon ti a ti rapada,
Yo tun gbe orin iyin na;
ff Ko Hosana, “Hosana loke orun”
Amin.
351
L.M.
Mo mo pe Oludande mi mbe. Jobu 19:25.

1. f Mo mo p’Oludande mi mbe
Itunu nla l’eyi fun mi!
p O mbe, Eni t’O ku lekan;
f O mbe, ori iye mi lae.

2. f O mbe lati ma bukun mi,


p O si mbebe fun mi loke,
ff O mbe lati ji mi n’boji,
Lati gba mi la titi lae.

3. cr O mbe, Ore korikosun


Ti y’o pa mi mo de opin,
f O mbe, emi o ma korin
Woli, Alufa, Oba mi.

4. O mbe lati pese aye


Y’O si mu mi de be l’ayo;
O mbe, ogo f’oruko Re;
Jesu okan na titi lae.

5. f O mbe, ogo f’oruku Re,


Olugbala kanna titi,
A! ayo l’oro yi fun mi:
f Mo mo p’Oludande mi mbe
Amin
352
C.M.
Oluwa, mu ise Re soji.Hab. 3:2.

1. mf Jesu Olugbala aye,


A ntoro ‘bukun Re,
Si ‘lekun aitase sile
Fun wara oro Re.

2. mf Ko awon to nu bo sile,
Gba won lowo esu;
cr Jeki won ri itewogba,
Ki won mo ‘gba anu.

3. mf Olufe okan: Iwo mo


Riri ohun t’O ra;
Wa f’ara han awon Tire
Pelu gbogb’ogbe Re.

4. Mu ki okan won lile ro,


Iwo t’O ku f’eda;
Fi eri ife Re han won;
Ese, owo, iha.

5. p Ese Re la kan mo igi,


K’O t’ese won mole;
Ana apa Re lati gba
Awon ti won pa O.

6. Iha Re ni ‘bi orisun,


Nibi gbogbo eda
cr Le lo mu n’nu omi iye,
Ki won we ‘ra won mo.

7. mf ‘Wo nfe f’eje Re jeri pe


Otito l’oro na;
Ogbe Re nke s’elese pe:
p Mo jiya yi fun o.
Amin.
353
C.M.
E gbe ori nyin soke enyin enu ona; ki Oba ogo wo inu ile wa. OD. 24:7.

1. f A gbe ilekun wura ro,


A si si won paya;
Oba Ogo si ti wole
Lo s’odo Baba Re.

2. mf Oluwa ‘Wo ti saju lo


Pese aye fun wa,
Ki a ba le wa lodo Re
Lati w’oj’Olorun.

3. Imole t’o logo ntan lae


Li ona aye wa;
Imole aye wa;
di Ti ko je ka ri O.

4. mf Jowo gbe okan wa soke,


F’ore-ofe fun wa
Ba ti nrin kiri l’aye yi
Ka ni ‘sura lorun.

5. f Ki ireti at’ife wa
Le ma wa l’odo Re;
Ma gbe ‘nu wa, ki a le wa
Ninu Re titi lae.
Amin.
354
6.6.6.6.8.8.
Jesu na yi, ti a gba soke orun yio pada be, bi e ti rii ti o nlo si orun.Ise. A. 1:11.

1. mf Eyin t’e f’Oluwa


To mo ‘pa Re, e wa,
E dapo n’isokan,
Lati yin ore Re,
F’orun at’aye, e kede
Oruko Oludande yin.

2. O f’ite Re l’oke
At’ogo Re sile;
O f’ife sokale,
O soku, O si ku;
Iya to je tani le wi
Lati gb’okan wa lowo iku?

3. Lati ‘boji; O nde


N’isegun lor’iku;
O k’awon ota Re,
To segun lat’ibe;
O si l’awon orun koja
N’isegun s’ite Olorun.

4. O fere pada wa,


Keke Re ki yo pe,
Lati m’omo Re lo
Si ile ailopin;
Nibe l’ao ri lojukoju,
L’ao ko isegun s’ite Olorun.

5. Jesu, a ko le san
Gbese ‘fe Re ta je,
Ko wa ba ti le san;
Gba ‘yin at’ope wa,
T’okan t’ara wa la fun O;
Bo tile kere, te ‘wo gba.
Amin.
355
8.7.8.7.D.
Owo otun Re, ati apa Re mimo, li o ti mu igbala wa fun ara Re. OD. 89:1.

1. f Wo Asegun b’O ti g’oke,


Wo Oba n’nu ola Re;
O gun keke ofurufu
Lo s’orun agbala Re;
Gbo orin awon angeli
Aleluya ni nwon nko,
Awon ‘lekun si si sile,
Lati gba Oba Orun.

2. mf Tani ologo ti mbo yi,


T’On ti ipe Jubeli
p Oluwa awon ‘mo-ogun,]
On t’O ti segun fun wa
p O jiya lor’agbelebu
O jinde ninu oku,
f O segun esu at’ese
Ati gbogbo ota Rre.

3. mf Bo ti nbuk’awon ore Re,


A gba kuro lowo won
Bi oju won si ti now lo,
O nu nin’awosanma;
Eni t’O ba Olorun rin
To si nwasu otito,
On, Enok’ wa li a gbe lo
S’ile Re loke orun.

4. mp On Aaron wa gbe eje Re


Wo inu ikele lo;
Joshua wa ti wo Kenan’,
Awon Oba nwariri;
mf A fi di eya Israel’
Mule nibi ‘simi won,
Elija wa si fe fun wa
N’ilopo meji Emi.

5. f Iwo ti gbe ara wa wo


Lo s’ow’otun Olorun:
A si joko nibi giga
Pelu Re ninu ogo;
ff Awon angeli mbo Jesu
Eniyan joko lor’ite;
Oluwa, b’Iwo ti goke
Jo je ka le goke be. Amin.
356
7.7.7.7.& Aleluya
Nigbati Oluwa si ti ba won soro tan, a si gba A lo soke orun. Mk. 16:19.

1. f Alafia f’ojo na - Aleluya


T’O pada s’ite lorun - Aleluya
p Krist’ t’a ti fifun eda - Aleluya
f Tun pada soke orun - Aleluya

2. ff Iyin duro de nibe - Aleluya


Gb’ori s’oke, ilekun - Aleluya
Si ogo orun paya - Aleluya
Je k’Oba ogo wole - Aleluya

3. f Orun, gba Oluwa re - Aleluya


mpSibe On feran aye - Aleluya
f Bo ti pada s’ite Re - Aleluya
mp Sibe O pe wa n’Tire - Aleluya

4. mpWo! O gbowo Re soke - Aleluya


Wo! O f’apa ife han - Aleluya
Gbo, bi O ti nsure fun - Aleluya
Ijo Re l’aye nihin - Aleluya

5. mf Sibe o mbebe fun wa - Aleluya


Ebe Re yo si bori - Aleluya
cr O npese aye fun wa - Aleluya
f On l’akobi iran wa - Aleluya

6. cr Oluwa lae lao ma ke - Aleluya


S’Iwo ti a gba soke - Aleluya
Pe, wo awa ‘ranse Re - Aleluya
Ba ti te ‘ju wa mo O - Aleluya

7. Bo ti je pe a gba O - Aleluya
Soke kuro lodo wa - Aleluya
Jo, je k’okan wa dide - Aleluya
Ba O lo soke orun - Aleluya

8. Nibe lao wa pelu Re - Aleluya


N’ijoba ayeraye - Aleluya
Nibe l’ao ri oju Re - Aleluya
Li orun awon orun - Aleluya
Amin
357
7.6.7.6.D.
Iwo ti goke si ibi giga. OD. 68:18.

1. f Kristi, l’ehin isegun


Iwo ti goke lo;
Kerub’ at’ogun orun
Wa sin O goke lo;
mf K’aye so ‘tan na jade,
cr Imanueli wa,
f Ti s’ara iy’ara wa,
Gori ite Baba.

2. mf ‘Lekun orun si sile,


Iwo ha le gbagbe
Awon to fe O, Jesu
Ti nwo lat’Olifi?
L’okan aya Re la ko
Oruko gbogbo si;
Alufa l’aye, l’orun,
Okan na l’ailopin.

3. mf Nibe lo duro, to nso


di Agbara eje Re;
O mbebe fun elese,
‘Wo alagbawi wa,
p Gbogbo ayida aye
T’ayo, t’aniyan wa
cr N’iwo nse iyonu si,
T’iwo si mbebe fun.

4. p Nitori itoye nla


Ti agbelebu Re,
K’O fi Emi Mimo Re
So ofo wa d’ere,
Nipa igbiyanju wa
Okan wa o goke;
Lati ba O gbe titi,
Li ayo ailopin.
Amin.
358
6.6.6.6.8.8.
E ho iho ayo si Oluwa, enyin ile gbogbo. OD. 100:1.

1. f Olorun goke lo
Pelu ariwo nla,
Awon ipe orun
Nf’ayo angeli han;
ff Gbogbo aye yo, ke gberin
E f’ogo fun Oba Ogo.

2. mpO j’eniyan laye,


f Oba wa ni loke;
Ki gbogbo ile mo
Ife nla Jesu wa.

3. f Baba fi agbara
Fun Jesu Oluwa;
Ogun angel’ mbo O;
On l’Oba nla orun.

4. f L’or’ite Re mimo,
O gb’opa ododo;
Gbogbo ota Re ni
Yio ku lo bere.

5. f Ota Re l’ota wa;


Esu, aye, ese;
Sugbon yo rehin won,
Ijoba Re yo de.

6. f Titi gbogbo aye


Tta f’ododo tun bi
Yo ba ogun orun
Gbe orin ayo nla.
Amin.
359
D.S.M.
Eniti o ti sokale li o si ti rekoja gbogbo awon orun. Efe. 4:10.

1. f Iwo ti goke lo
S’ile ayo orun,
Lojojumo y’ite Re ka
L’a ngbo orin iyin;
P Sugbon awa nduro
Labe eru ese;
cr Jo ran Olutunu Re wa,
Ko si mu wa lo ‘le.

2. f Iwo ti goke lo
p Sugbon saju eyi,
O koja ‘rora kikoro
cr Ko to le de ade;
mp Larin ibanuje,
L’ao ma te siwaju;
cr K’ona wa to kun f’omije
To wa si odo Re.

3. f Iwo ti goke lo
Iwo o tun pada;
Awon egbe mimo loke
Ni yo ba O pada
mf Nipa agbara Re,
K’a wa, k’a ku n’nu Re,
cr ‘Gbat’a ba ji lojo ‘dajo,
f Fi wa si otun Re.
Amin.
360
7.7.7.7.D
A gbe E soke; awosanmo si gba A kuro li oju won. Ise A. 1:9.

1. p O ti lo, awosanmo
Ti gba kuro loju wa
f Soke orun, nibiti
Oju wa ko le tele;
O ti kuro l;aye yi,
O ti de ibi mimo,
Lala ati ‘rora tan,
Ija tan, O si segun.

2. p O ti lo, awa si wa
L’aye ese at’iku,
A ni ‘se lati se fun,
L’aye to ti fi sile
cr Ka si tele ona Re;
Ka tele tokantokan,
Ka s’ota Re di ore,
Ka fi Krist’ han n’iwa wa.

3. p O ti lo, On ti wipe,
“O dara ki Emi lo”
Ni ara sa lo ya wa,
Sugbon or’ofe Re wa,
mf On ni awa ko ri mo
A ni olutunu Re;
f Emi Re si jo ti wa,
O ns’agbara wa d’otun.

4. p O ti lo, l’onakanna
Lo ye k’Ijo Re ma lo
Ka gbagbe ohun ehin
f Ka si ma tesiwaju,
Oro Rre ni ‘mole wa
Titi de opin aye
Nibiti oto Re wa
Yo pese fun aini wa.

5. p O ti lo, l’ekan si i
A o tun foju wa ri;
O wa bakanna lorun
Gege b’o ti wa l’aye;
N’nu ‘bugbe to wa nibe
Yo pese aye fun wa;
p Ninu aye ti mbo wa
A o j’okan pelu Re.

6. p O ti lo fun ire wa,


E jeki a duro de,
f O jinde ko si nihin,
O ti goke re orun,
Je ka gb’okan wa soke
Sibiti Jesu ti lo,
Si odo Olorun wa
ff Nibe l’alafia wa.
Amin.
361
10.10.10.10.
Emi nlo, lati pese aye sile fun yin. Jn. 14:2.

1. f E gbo iro orin ayo orun,


Orin ayo ti isegun Jesu;
Gbogbo ota l’o teri won ba fun,
p Ese, iku, isa-oku pelu.

2. f O se tan lati lo gba ijoba,


fun Baba olorun ohun gbogbo;
O se tan lati lo gba iyin nla,
T’o ye olori ogun’gbala wa.

3 p Ohun iknu ni lilo Re, fun


Awon ayanfe omo eyin Re.
f E ma se konnu l’ oroit unu,
“Emi nlo pese aye yin sile.”

4 Orun gba lo kuro leyin eyi,


Awonsanma seolugbala mo:
ff Awon ogun-ho fun ayo,
Fun bibo Kristi Oluwa ogo.

5 mp E mase ba inu yin je rara,


Jesu, ireti wa, yio tun wa;
F Yoo wa mu awon eeyan Re lo
Sibiti won oba gbe titi lae.
Amin.
362
6.6.6.6.8.8
A wa ni olori Aluf nla kan ti o ti koja lo sinu awon orun. Heb. 4:14.
.
1 f Onigbagbo, e wa,
Isreali t’emi;
K’a fi ayo pejo
K’agboyin didun yi;
ff Jesu goke, O lo s’orun,
Alufa giga, wa r’orun

2. mf Ojo etutu de,


Isreali, e p;
P A ti ru ebo tan
Ebo Odagutan;

3 Ibi mimo julo,


L’Olugbala wa lo,
mp Pelu eje mimo
T’O ju t’ewure lo:

4. ff Kristian, e ho f’ayo,
Olorun gb’ebo wa;
f Jesu mbebe pupo,
Bi Alagbawi wa;
ff Enikeni t’o fori fun,
Y’o ni iye ainipekun.
Amen.

363
C.M
Bi o ti nsure fun nwon, a ya a kuro
lodo nwon a si gbe lo si orun. Lk. 24:51

1. A ha iho ayo mimo


S’Olorun Oa nla
K’ile gbogbo lo ahon won
K’o si ko ‘rin segun.

2. Jesu Oluwa wa goke


Eso orun yika,
Won ba goke bi O ti nlo
Pelu iro fere.

3. B’angeli ti nyin Oba won


K’eda ko orin na:
Ki aye korin ola Re:
O joba gbogb’aye

4. F’iberu na wa iyin Re
Fi oye korin na,
Ma fi ahon etan fun u
Nipa iyin eto.
Amin.
364
11.11.11.11
E mase pa ina Emi. 1 Tess 5:19.

1. mf Iwo elese, emi nfi anu pe


Okan re to ti yigbi ninu ese:
Mase ba Emi ja, ma pe titi mo,
Ebe Olorun re le pari loni.

2. f Omo Ijoba, ma s’eru ese mo.


Gb’ebun Emi mimo ati itunu,
Ma bi emi ninu, Oluko re ni;
Ka ba le se Olugbala re l’ogo.

3. p Tempili d’ibaje, ewa re d’ile


Ina pepe Olorun fere ku tan;
Bi a fi ife da o si le tun ran,
Mase pa’na emi, Oluwa mbo wa
Amin.
365
9.4.9.4.& Ref.
Emi mi si yo si Olorun Olugbala mi. Ku 1:47

1. mf O kan mi sipaya, Oluwa,


Wole wole
Igbagbo mi ro mo oro Re
Wole wole.
f Ma b mi gbe titi Oluwa,
Ohun ti O fe ni un o fe
Fi okan mi se ‘bugbe Re laelae
Wole wole

2. mf Beni aye mbe fun Oluwa


Wole wole
‘Dide Re mu mi sun mo O si
Wole wole

3. mpMo da O duro s’ode pe je


Wole wole
Dari eyi ji mi Oluwa
Wole wole

4. p Mo gbo, O nkan ‘lekun, Oluwa


Wole wole
Nko ni da O duro s’ode mo
Wole wole
Amin.
366
8.7.8.7.& Ref.
Sugbon enyin o gb agbara,
nigbti emi Mimo ba ba le nyin Ise A 1:8

1. mf ‘Gbat agbra Olorun de,


Li ojo pentikosti,
Sa if oju s’ona pari
‘tori won ri Emi gba .
ff Ran agbara, Oluwa,
Ran agbara, Oluwa,
Ran agbara, Oluwa,
Ki O baptis’ wa

2. f Ela ‘han ina ba le won


won si wasu oro na.
Opolopo eeyan gbagbo
Won yipada s’Olorun.

3. f A nw’ona fun emi mimo


Gbogbo wa f’ohun sokan
Mu ‘leri na se Oluwa
Ti a se nin’oro Re.

4. f Jo, fi agbara Re kun wa,


Fun wa ni ‘bunkun ta nfe:
Fi ogo Re kun okan wa,
Ba ti nfi’gbagbo bebe.
Amin.
367
L,M
Emi o tu ninu Emi mi jade sara eniyan gbogbo Ise A 2:17

1. mf Oluwa, awa gbagbo pe


Tiwa ni ‘ileri igbani:
A nret’ agbara petikost,
Emi mimo lat’oke wa

2. mf Fun gbogb’eni ti krist pe


ni ‘leri to daju mbe fun:
O npe gbogbo eyin Tire
E gba oro ti jesu so.

3. mp Ma je ka s’ofo pe titi
N’ifojusona bibo Re,
cr Ran Olutunu sokale,
K’alejo orun ba wa gbe.

4. mf A f’okan kan pejo nihin,


A nreti’ ileri or-ofe
Tiku Oluwa wa ti ra:
Emi mimo wa kun ihin

5. B’eni bere ba le ri gba


Bo ba mba l’ese sibe,
Wa b’iro efufu lile
Fun gbogbo wa lor’ofe Re

6. Sa wo, Iwo lokan wa nwa,


A si npongbe isokan Re:
cr Da ina iye sinu wa
Fi okan wa se’bugbe Re
Amin.
368
CM
Emi o tu Emi mi jade sara eniyan gbogbo joe.2:23.

1. mf Emi mimo, s’okan wa,


ka mo agbara Re:
cr Orisun emi ‘sotele,
T’imole at’ife.

2. mf Emi mimo l’agbara Re


L’awon woli sise;
Iwo lo nfi oto han wa,
Ninu iwe mimo.

3. mf Adaba orun, na ‘ye Re


Bo okun eda wa:
Jeki ‘mole Re tan sori,
di Emi aisoto wa.

4. mf A o mo, Olorun daju


B’Iwo ba mbe n’nu wa
Ao mo ‘jinle ife mimo
Pelu awon Tire.
Amin.
369
8.6.8.4.
Emi o si bere lowo babaon o soi fun
Nyin li Olutunu miran ki o le ba nyin
Gbe titi. Jn 14:16.

1. mp Olurapada wa, k’On to


Da gbere ikehin,
‘ o fi Olutunu fun ni,
Ti mba wa gbe

2. p O wa ni awo adaba,
O na iye bo wa:
O tan’ fe on alafia
S’ori aye.

3. mf O de, O mu ‘wa rere w


Alejo Olore:
‘Gbat’ O ba r’okan irele
Lati magbe

4. p Tire l’ohun jeje ta ngbo,


Ohun kelekele:
Ti mbani wi, ti ni l’eru lo
ti nso t’orun.

5. Gbogbo iwa rere ta nhu


Gbogbo isegun wa:
Gbogob ero iwa mimo
Tire ni won.

6. mf Emi mimo Olutunu,


Fi ‘yonub wa wo,
cr Jo s’okan wa ni ‘buge Re
Ko ye fun O.
Amin.
370
CM
Emi Olorun si nrababa loju omi .Gen 1:2

1. f “Gbani t’Olorun sokale,


O wa ni ibinu,
Ara si nsan miwaju Re,
Okunkun oun ina.

2. p Nigbat’ O wa nigba keji,


O wa ninu ife:
pp Emi Re si ntu ni lara
emi ore ofe.

3. f Ina sinai ijo kini,


T’owo re mbu s’oke,
mp Sokale jeje bi ade,
Si ori gbogbo won.

4. f Bi ohun eru na ti dun


L’eti Isreli,
B’iro ipe, ti angeli
Wariri lati gbo.

5. mf Be gege nigbat’ emi wa


Ba le awon Tire,
cr iro kan si t orun wa:
Iro iji lile.

6. f O nkun ijo Jesu, okun


Aye ese yi ka,
mp L’okan alaigboran nikan
Ni aye ko si fun

7. mf Wa, Ogbon, Ife at’Ipa:


fun w leti igbo:
p k’a ma so akoko wa n:
ki ‘fe Re le gba wa.
Amin.
371.
CM
Nwon si kun fun emi mimo Ise A 2:4

1. mf ‘’W o Olorun Emi


l’ojo ‘tewogba yi
Gege bi ojo petikost’
Sokale l’agbara,
L’okan kan la pade
Ninu ile Re yi:
A duro de ileri Re,
p emi ore ofe.

2. p b’iro iji lile


Wa kun nu ile yi:
cr Mi emi isokan si wa:
Okan kan, imo kan:
Fun ewe at’agba
L’ogbon at’oke wa;
Fi okan gbigbona fun wa
Ka yin, ka gbadura.

3. mp Emi imole, wa
Le okunkun jade,
Siwaju ni ki ‘moe tan
Titi d’osan gangan,
Emi otito, wa
Samoma wa titi;
Emi isodomo, si w
S’okan wa di mimo.
Amin.
372
8.8.8.D.
emi Olorun si nra baba loju omi Gen 1:2.

1. mf emi eleda, nipa Re


la f’ipile aye sole:
p Ma sai be gbogo okan wo,
Fi ayo re si okan wa,
Yo wa nin ‘ese at’egbe,
Ko fi wa se ibugbe Re.

2. f Orisun Imole ni O,
Ti baba ti se ileri
Iwo ina mimo orun
F’ife orun kun okan wa;
p Jo tu ororo mimo Re
S’ori wa bi ati nkorin

3. mp Da opo ore-ofe Re
Lat’ s’ori gbogbo wa:
cr je ka gba otito Re gbo,
Ka si ma saro l’okan wa;
F’ara Re han wa ka le ri
Baba at’Omo ninu Re.

4. f ka fi ola ati iyin


Fun Baba, Olodumare,
K’a yin oko Jesu logo;
Eni t’o ku , lati gba wa:
Iyin bakanna ni fun O
Parakliti ayeraye.
Amin.
373
C.M
Iwo so mi idi aye gege bi oro Re OD.119:25

1 mf Emi mimo ‘Daba orun,


cr Wa li agbara Re;
Ko da ina ife mimo
Si okan tutu wa.

2. cr Wo ba ti nra pala nihin


Ta fe ohun asan ;
Okan wa ko le fo ko lo
Ko de b’ayo titi.

3. Okan ao ha wa titi
p Ni kiku osi yi?
Ife wa tutu be si O
Tire to bi si wa.

4. f Emi mimo ‘Dabo orun


cr Wa ni agbara Re
Wa da ‘na ‘fe Olugbala
Tiwa o si gbina.
Amin
374
7.7.7
Emi o si fi Emi titun sinu yin.Esek.11.19

1. mp Wa. Parakiti mimo,


Lat, ibugbe Re orun;
cr Ran itansan ‘mole wa

2. mf Baba talaka ,wa ‘hin


Olufunmi l;ebun wa,
Imole okan ,jo wa

3. p Baba Olutunu, wa
Alejo toto f’okan ,
Pelu itura Re ,wa

4. mf Wo n’isimi n’n’nu lala


Iboji ninu oru,
Itunu ninu, ponju.

5. p Wo mole to mo gara ,
cr Tan sinu aye awon
Eniyan Re oloto.

6. Laisi Re kil’ eda je?


Ise at’ ero mimo
Lat’ Odo re wa ni won.

7. p Eleri, so di mimo
Agbogbe, masai wo san,
Alaisoeso mu s’eso.

8 Mu Okan tutu gbona,


M’ alagbidi teriba
Pe asako wa jeje.

9 cr F’emi’ jinle Re meje


Kun awon oloto Re
F’ agbara Re s’abo won.

10 f Ran or-ofe Re , sihin,


Ekun igbala l’orun
Amin
375
8.8.8.D
Nitori eso emi wa ni ti ohun rere gbogbo , ati ododo , ati otito, Efe.5:9

1. mf Wa, mi si wa ,Emi Mimo ,


Tan ‘na orun si Okan wa;
Emi a f’ ororo yan ni;
Ti f’ ebun meje Re fun ni;
Ise itunu, iye ,na ife

2 F’ imole Re igba gbogbo


Le okunkun okan wa lo;
mf F’ ororo ore-ofe Re
Pa oju eri wa ko dan ;
di L’ ota jina si bugbe wa;.
P Ire n’igbe biti Wo nso.

3 mf Ko wa, ka mo Baba , Omo


Pelu Re li okansoso
cr Titi aye ainpekun ,
Ni k’eyi je orin wa.
f Lae, iyin , eye ni fun O,
Baba , Omo Emi Mimo
Amin
376
L.M
Iye awon ti a fi Emi Mimo Olorun to, awon ni ise Omo Olorun.Rom. 8:14

1 mf E mi Mimo ‘ Daba orun,


Wa ma itunu sokale ;
f Se Oga at’ Oluto wa
Ma pelu gbogbo ero wa,

2 mf Jo a le fe han wa,
Ka le fe, ka si ona Re
P Gbin ife totos’okan wa,
Ka ma le pada lehin Re.

3 cr Mu wa ka to ona mimo;
Ta le gba d’odo Olorun;
Mu wa to krist’ ona iye,
Ma je ki awa sina lo,

4 f Mu wa t’ Olorun ‘simi wa,


Ka le ma ba gbe titi lae;
To wa s’orun , ka le ipin
L’owo otun Olorun wa,
Amin
377
“Ogo Olorun si kun ile Olorun” 2Kro. 5:14.

1. mf Emi orun gb’adura wa


Wa gbe ‘nu ile yi
Sokale pel’agbara Re
f Wa, Emi Mimo wa.

2. mf Wa bi ‘mole si fi han wa
B’aini wa ti po to
Wa to wa si ona iye,
Ti olododo nrin.

3. Wa bi ina ebo mimo


Sokan wa di mimo
Je ki okan wa je ore
F’oruko Oluwa.

4. p Wa bi iri si wa bukun
Akoko mimo yi
cr Ki okan alaileso wa
Le yo l’agbara Re.

5. p Wa bi adaba n’apa Re
Apa ife Mimo
Wa je ki’ ijo Re l’aye
Dabi ijo t’orun.

6. f Emi orun gb’adura wa


S’aye yi dile Re
Sokale pel’agbara Re
Wa Emi-Mimo Wa.
Amin
378
7.7.7.6.
Emi o dabi iri si si Iraeli Hos.14:5

1 mf Emi ‘bukun ti a nsin


Pelu Baba at’ Oro,
Olorun ayeraye;
P Gbo wa, Emi mimo.

2 cr Iwo Adaba orun


Iri ti nse lat’ oke;
Emi ye at’ iwa ‘fe
P Gbo wa, Emi mimo.

3 mf Isun ipa at’ imo,


Ogbon at’ bisi igbagbo ,
O ye, imoran , eru;
p Gbo wa, Emi mimo.

4 mf Isun ife alafia


Suru ‘bisi igbagbo
Reti ayo ti ki tan,
p Gbo wa, Emi mimo.

5 cr Emi af’ ona han ni,


Emi ti nmu ‘mole wa
Emi agbara gbogbo
P Gbo wa, Emi Mimo.

6 mp Wo t’o mu Wundia bi,


Eni t’aye mbo,
Ta ran lati tun wa bi,
p Gbo wa , Emi Mimo.

7 cr Wo ti Jesu t’oke kun ljo,


Wa tu eniyan Re ninu,
Ki nwon ma ba nikan wa,
p Gbo wa. Emi Mimo.

8 Wo t’O nf’ore kun ljo


T’O nfi ife Baba han,
p Gbo wa, Emi Mimo.

9 mf Iwo ti nf’ onje iye


At’ otito na bo wa
Ani, on to ku fun wa
p Gbo wa, Emi Mimo.

10 mf F’ebun meje Re fun ni,


Ogbon lati m’Olorun,
Ipa lat’ ko ota,
p Gbo wa, Emi Mimo

11 mf Pa ese run l’okan wa,


To ife wa si ona ,
Ba ba nse O mu suru;
p Gbo w, Emi mimo.

12 cr Gbe wadide, ba subu,


Ati nigba idanwo
Sa pe wa pada pele
p Gbo wa, Emi Mimo

13 mf Wa k’O mu ailera le.


`F’igboya fun alare,
Ko wa l’oro tra o so;
p Gbo wa, Emi mimo.

14 mf Wa ran okan wa lowo,


Lati mo otito Re,
K’fe wa le ma gbona,
p Gbo wa, Emi mimo.

15 mf Pa wa mo l’ona toro,
Ba wa wi gba ba nsako
Ba wa bebe l’adura,
P Gbo wa, Emi mimo.

16 mf Emi Mimo , Olufe,


Wa gbe inu okan wa.
Ma fi wa sile titi.
p Gbo wa, Emi Mmimo.
Amin
397
S.M
Sugbon enyin o gba agbara nigbati Emi Mimo ba ba le yin. Ise A .1:8

1 mf Emi alagbara ,
Wa joko ninu mi.
Ki O si fun wa n’idande
Low’ eru on ese.

2 cr Emi iparaele
Gbe arun ese lo.
Emi iwa mimo pipe
Emi ife pipe.

3 M’ojo na yara de,


Ti ao run ese mi.
T’ohuin atijo yo koja,
T’ohun gbogbod’otun.

4 di Ese abinbi ,
Pare li okan mi;
cr Wole ki O si le jade,
Gba gbogb’ okan mi kan.

5 mf Oluwa, mo fe ni,
Eri pe, mo nse re
Gegebi fe at’ oro Re.
Bo ti to oju Re.

6 di Ko fe ipo giga;
Sa fi eyi ke mi.
Ni gbakugba to ba si ya.
p Gbo mi s’ orun rere .
Amin.
380
8.6.8.8.6.&.Ref
Enyin ha gba Emi Mimo na nigbati enyin gbagbo ? Ise A. 19:2.

1 mp “Emi ki y’o fi yin sile”


Laini Olutunu,
Emi yo ran Olutunu
Ti yo ma ba yin gbe titi,
Losan ati l’oru.
mf Emi na ti de sodo re bi?
Olutunu na ha ti de?
Yo fi oye ese ye aye
“Gbati Olutunu ba de.

2. Ijo Kristi e dide gba


Ekun agbara yi,
Titi ao mu gbogb’ asako
Wa sabe ore-ofe Re,
Nipa gbigba Jesu.

3. mf Orun kun fun Pentikosti


Fun gbogbo eniyan,
Je ka fi irele bere
Ileri wa ninu Kristi,
Agbara lat’orun.

4. p Ka tun pada si Pentikost’


Si iyara oke,
Ka gbadura s’Oluwa wa
K’Oran Emi Mimo si wa
Ka fi suru duro.
Amin.

381
8.8.8.8.8.8.
Ki ise ami ati ise iyanu ki o ma se ti Oruko Jesu. Ise A.4:30.

1. mf Awa pejo s’iwaju Re


Lati kede ‘gbala kikun:]
Lati jewo ore ta gba
Nipa Oruko nla Jesu:
Tewogb’ope wa, Oluwa
Te ongbe okan wa lorun.
2. mp Awa mbe O, lakoko yi
F’agbara Pentikosti han;
‘Gbati awon ti ongbe ngbe
Ri ‘dariji on ‘wenumo,
La oju awon afoju,
Si eti awon to di ‘ti.

3. p Awon ti eru ese npa


Mbe nihin lati gba ‘wosan;
Gbogbo awon ta npon loju
Lo wa fun idasile won
Soro ‘wosan ki gbogbo won
Le gba iwenimo okan.

4. f F’igboya f’awon ‘ranse Re


Ki won wasu tikantokan;
Na owo Re lati wosan
K’ise ‘yanu se l’oko Re,
Ka ri agbara Re loni
Ka le gbe oruko Re ga.

5. cr Awa nduro bi O ti wi
Je ko ri fun wa b’oro Re,
K’aigbagbo tab’igberaga
Mase dena agbara Re,
Joba ninu okan gbogbo,
Awa mbe O, Emi Mimo.
Amin.

382
8.7.8.7.D.&.Ref
Emi o da omi lu eniti ongbe ngbe. Isa.44:3.

1. mf A wa pejo l’oruko Re
Ninu ile mimo yi.
Ibukun Baba wa la nfe,
A mbere or’ofe Re;
Lat’inu ekun ‘bukun Re
Ti o jin ju okun lo,
Ro ojo na si wa lori
Ko fi so wa d’ominira.
f Si ferese orun sile
Ro ojo na s’ori wa;
Ro ojo igbala kikun,
We gbogbo abawon nu.
2. f Si ferese orun sile,
Ro ojo na sori wa,
Yo wa kuro n’nu iparun,
Gbe wa soke to ga ju;
Ki opo awon elese
Le wa to ife Re wo;
Ka gba won sinu ‘joba Re
Nipa ‘wenu atubi.

3. f Awa gbagbo pe O mbowa,


Ojo ‘bukun na nbowa;
Iwo eniti ngbadura,
Na apa agbara Re,
Ojo agbara lat’oke
Ojo ife Kalfari;
Mu ago wa kunwosile,
Ro ojo nla lat’oke.
Amin.

383
S.M.
O mi si won. Jn.20:22.

1. cr Mi si mi, Olorun,
F’emi titun fun mi,
Ki nle fe ohun ti O fe,
Ki ns’eyi t’O fe se.

2. Mi si mi, Olorun,
S’okan mi di mimo,
K’ife mi on Tire j’okan
L’ero ati n’ise.

3. Mi si mi, Olorun,
Titi un o di Tire,
Ti ara erupe mi yi
Yo tan ‘mole orun.

4. mp Mi si mi, Olorun,
Emi ki yo ku lae,
Un o ba O gbe n’iwa pipe
Titi ayeraye.
Amin.
384
11.10.11.10.
Nitoripe Olorun wa, ina ti ijonirun ni. Heb.12:29.

1. mf Ina Emi Orun, ma jo ninu mi,


Da ‘na iwa mimo si okan mi
Orisun ‘mole at’ibukun gbogbo,
So aye mi di t’imole titi.

2. cr Ina Emi Orun, je k’ogo Re tan,


S’okan mi di mimo fun ogo Re;
Wa da ‘na ife orun si okan mi:
Ife ti njere okan f’Oluwa.

3. Ina Emi Orun, ba le mi loni,


Ela ahon bi t’ina ba le mi,
Mu eyin-ina lati pepe orun;
Fi kan mi l’enu ki njise fun O.

4. f Ina Emi Orun, ni igba meje


We mi, tun mi we, ki nle r’oju Re;
Titi aworan Re yo han lara mi
Ki nle ri iran Kristi ju be lo.

5 ff Ina Emi Orun f’ife Re kun mi,


Ki gbogbo aye mi le di Tire;
Emi, okan, ara mo fi won rubo,
Ran ina sori ebo na loni.
Amin.

385
7.7.7.D
Emi otito ni yio si wa ninu yin Jn.14:17

1 cr Emi ore , bami gbe,


Emi o si d’olore,
Pelu oro isore
Ni un o fi emi Re han,
Nn’igboya at’ irele
L’emi o soro Kristi.

2 di Emi Oto, ba mi gbe,


Emi o si d’ototo,
Pelu ogbon to daju
Ni un o fi emi Re han,
Ni ife arakunrin
Ni un o s’oto Oluwa.

3 mp Emi Tutu, ba mi gbe,


Emi o si di tutu,
P’okan mi mo b’ itanna
Li akoko idanwo;
Si sile n’gba orun nran.
F’ orun ,didun yin ‘fe Re.

4 mf Emi ipa,ba mi gbe


Emi o si Lagbara,
Agbara lati bori
Un o ti ipa eeyan pin,
Ninu ‘reti titi lae.

5 f Emi Mimo, ba mi gbe


Emi o si di mimo ;
Emi o ya fun ese.
Emi yan ohun re.
Ohun ti mo ba si ni,
Un o fun Eni to dami,
Amin

386
8s..7s.
Gbogbo won si kun fun Emi MimoIse A.2:4

1 f Baba wa orun , awa de,


p Awa alailagbara ;
cr Fi Emi mimo Re kun wa.
K’o so gbogbo wa d’otun
f Wa, Emi Mimo jare wa.
F’ede titun s’okan wa.
Ebun nla Re ni l’a ntoro
T’ojo nla pentikositi.

2 f Ranti ileri Rre Jesu


Tu Emi Re s’ara wa,
Fi alafia Re fun wa.
Ti aye ko le fi fun ni,
f Wa, Emi Mimo jare wa.
Pa ese run l’okan wa,
Ebun nla Re ni l’a ntoro,
T’ojo nla pentikositi.

3 Adaba orun ba le wa.


f Fi agbara Re fun wa,
Ki gbogbo orile-ede
Teriba f’Olugbala ,
K’a gburo Re jakelado.
Ile okunkun wa yi,
Ebun nla Re ni l’a ntoro
T’ojo nla pentikosti.
Amin
387
7.3.7.3.7.7.7.3

Kiyesi, mo duro li enu ilekun, mo si nkankun. Ifi. 3:20.

1. mp Alejo kan ma nkan ‘kun


Pe wole,
O ti pe to ti npara;
Pe wole
Pe wole ki o to lo;
Pe wole, Emi Mimo
cr Jesu Krist’Omo Baba
Pe wole.

2. mp Si okan re paya fun,


Pe wole,
di B’o ba pe y’o pada lo,
Pe wole,
cr Pe wole, ore re ni;
Yo pa o mo de opin;
Pe wole.

3. mp O ko ha gbo ohun Re
Pe wole
Se l’ayanfe re loni,
Pe wole,
O duro l’ehin ‘lekun
cr Yio fun o li ayo
‘Wo o yin oruko Re
Pe wole.

4. mf Pe alejo na wole,
Pe wole,
Yio se ase fun o
Pe wole
cr Y’o dari ese ji o
‘Gbati ipinya ba de,
Y’o mu o dele orun,
Pe wole
Amin.
389
1. f Jise Re nde, Jesu
Fi agbara Re han
ff Fo ‘hun to le j’oku dide,
Mu keniyan Re gbo
f Ji ‘se re nde Jesu
‘Gba ta nsin O, nihin
Sokale wa olore wa
Si bukun wa nihin

2 f Ji’se re nde Jesu


Mu k’ongbe re gbe wa,
Si mu k’ebi pa okan wa;
Fun onje iye na.

3. mf Ji’se re nde Jesu


F’agbara f’oro re
Ka gbo ‘hinrere ‘bukun re
Ni igbagbo aye.

4. mf Ji’se re nde Jesu


Gbe oruko re ga
Mu k’ife re kun okan wa,
Nipa Emi Mimo.

5. cr Ji’se re nde, Jesu


Ro’jo itura re
ff Ogo yoo je tire nikan
Sokale wa olore wa
Si bukun wa nihin.
Amin

390
8.7.8.7.&Ref.
Igbagbo re gba o la.Lk.7:50
1 f Nipa igbagbo ninu Krist’
Awa bo lowo ese.
Nipa gbigbekel’oro Re.
A bo low’ ero kero,
mf A nfi gbagbo rin l’okunkun ,
A nfi gbagbo tele Krist’ Imole,

2 cr Ona iye rorun to,


Ka gbekele Krist’ nikan;
Aro on ija re yo pin
Bi iwo ba je gba A.

3 mp Iku Jesu lo san ‘gbese


Ki se ara on ronu,
O ti ru ebi ese wa,
A fi okan re fun Un.

4 mf A nfi gbagbo rin l’okunkun ,


Imo yi tobi to,
Ona Olorun pa l’eyi,
Ma gbekele ero re,
Amin

391
11.11.11.11.&Ref
Kki emi enikan ti o ba gba A gbo ma ba segbesugbon ki o le ni iye ainipekun.Jn.3:16
1 mf Enikan ti o ba gba Jesu gbo,
T’o si gba ise ori agbelebu,
Yio ri igbala kikun gba l’ofe,
f Tori Kristi l’agbara lati gbala ,
f Eyin ayanfe , Olugbala npe yin.
Ayanfe , Oolugbala de O si npe yin
Or-ofe ati anu Rre je ‘yanu
Ore-ofe ati anu Re je ‘yanu
mp O ta eje Re sile fun irapada
O ta eje Rre sile fun irapada
f Oun si ni agbara lati gba ni la.
O si ni agbara lati gbala.

2 cr Enikan to ba ihinrere,
To si gbekele Re eje Re fun wenu
Yo ri irapada ti ayeraye
f ‘Tori O ni agbara lati gbala.

3 mp Eni to ba ko gbogb’ ese sile


Ti o si s’okan re paya f’Oluwa,
f Yo ni igbala pipe nisisiyi ;
‘Tori oun ti mura tan lati gbala.
Amin
392
S.M.& Ref.
Jesu wipe, Emi li ona , atioto ati iye, Jn.14:6
1 mf Jesu wipe oun li ona,
Emi o si tele;
Mo mo pe lehin okunkun
Imole yo si de.
mf Oun li ona , oto ati iye
Ko s’ona mi s’odo , oto at’ iye
Oun li ona , oto at’ iye
Ko s’ona mi s’odo Baba , af’ odo Re.

2 f Oun li oto, oto yo si


Je ‘mole ti nto mi,
Oko mi yo koja okun
Sile alafia ,

3 ff Oun ni iye ko si iku


Ti yo fo mi l’aya
Nitori nipa eje Re.
Mo ngbe nu’ Re titi.
Aamin
393
7.7.7.D
Wo o, Odo-agutan Olorun Eeniti o ko ese aye lo.Jjn.1:29
1 mp L’ekan mo ba ese ja,
‘Gbat’ o njoba l’okan mi,
Tit’ Olugbala fi de
mf O si segun gbogbo won
Nigbat’ o gbo ebe mi.
O si ko ese mi lo,
mf O ko gbogbo re,
Kristo Jesu ko ese mi lo,
f Itelorun ti de,
Emi Re ti de
Bi Jesu ti k’ese mi lo,

2 f Agbara ise ‘yanu


Ni wakati didun na.
Ti Jesu ba mi soro,
Mo gb’ oro yebiye na
Lat’ enu Oluwa mi
Gbati o da mi ni’de.

3 mf Iwo nja fun rere bi,


Jesu ni gbogbo ipa
Y’o segun ese fun O,
On t’o gba agbara re,
On y’O si ma ba o gbe
Y’O si fun o ni’simi.
Amin

394
10.7.10.7.&Ref
Kiyesi, emi mbo kankan ; ere mi si mbe pelu mi, Ifi.22:12
1 cr ‘Gba Jesu de lati f’ere fun wa,
Yala osan tab’ ale ,
Y’o ha ba wa, ka ma f’oto sona,
K’atupa wa si ma jo?
mf A ha le wipe , a se tan ,ara
Fun ‘le wa didan l’oke?
Wi, y;o ha ba wo at’ emi nsona?
Nsona n’gb’Oluwa o de?

2 mp Nje bo ba je oro kutukutu ,


T’O ba pe wa ni kokan ,
‘Gbat’ a ba da Talenti wa pada,
Y’o ha wi fun o, ‘o seun?

3 di A ha soto, s’eyi t’O fi fun wa?


Gbogbo ipa wa la nsa
Ti ko ba si dalebi l’okan wa.
f Simi ologo lao ni,

4 mf Bukun l’awon ti Krist’ ti to nsona,


Won o pin nin’ogo Re,
Bi l’aro tabi oganjop oru,
Y’o ha ba wa be nsona?
Amin
395
8.5.8.3.
On ni Olusesan fun awon ti o arabale wa, Heb 11:6
1. mp Are mu o, aye su o ,
Lala po fun o
mf Jesu ni, wa si odo mi
p K’o si mi.

2. mf Ami wo l’emi o fi mo
Pe on l’o npe mi?
Am’iso wa lowo, ati
Ese Re.

3. mf O ha ni ade bi oba,
Ti mo le fi mo?
cr Toto, ade wa lori Re
p T’egun ni.

4. mf Bi mo ba ri, bi mo tele,
Kini ere mi?
p Opolopo iya ati
‘Banuje.
5. mf Bi mo tele tit’aye mi,
Kini n go ri gba?
f Ekun a d’opin, o simi
cr ‘Tit’aye

6 mf Bi mo tele tit’ aye mi


Y’o ko fun mi bi?
f B’orun at’ aye nkoja lo,
p Ko je ko,

7 cr Bi mo ba ribi mo tele,
Y’o ha bukun mi?
ff Awon ogun orun wipe,
Yio se,
Amin
396
.7.5.7.6.& Ref
Pelu ipinnu okan , e fi ara mo Oluwa Ise A.11:23
1 mf Duro pelu okan kan,
Se ;fe Olorun;
Yin awon olotito
cr Se gegebi Daniel;
Ma wo enikan ;
Ni ero rere l’okan
Si je aye mo.

2 mp Oopo akin lo nsegbe


Won ko to duro;
cr Bi won wo egbe Daniel
Won ba ja f’ Olorun,

3 mf Opo lopo omiran


Ti nhale kiri
Ni iba susbu lule
B’egbe Daniel ko won,

4 f Gb’ opagun ‘hinrere ga,


E ma segun nso;
Pe ogun esu nija;
Ho ye f’ egbe Daniel.
Amin
397
7.6.7.6.8.8.7.&.Ref.
E wo iru ife ti Baba fi ife wa, I Jn 3:1

1. f Itan iyanu t’ife!


So fun mi l’ekan si,
Itan iyanu t’ife
E gbe orin na ga!
Awon angeli nroyin re
Awon oluso si gbagbo
Elese, iwo ki yo gbo
Itan iyanu t’ife
ff Iyanu! iyanu! iyanu!
Itan iyanu t’ife.

2 . Itan iyanu t’ife


B’iwo tile sako
Itan iyanu t’ife
Sibe o npe loni
cr Lat’ori oke kalfari,
Lati orisun didun ni.
Lati isedale aye,
Itan iyanu t’ife.

3 f Itan iyanu t’ife


Jesu ni isimi
Itan iyanu t’ife
Fun awon oloto
To sun ni ile nla orun
Pe l’awon to saju wa lo;
Won nko orin ayo orun
Itan iyanu t’ife
Amin.
398

7.7.7.7.&Ref
Nitori ajaga mi rorun, eru mi si fuye,Mat. 11:30
1 f Jesu y’o gba elese
Kede re fun gbogb’eda;
di Awon ti won sako lo,
Awon ti won subu.
ff Ko l’orin ko si tun ko,
Kristi ngb’ awon elese
Fi oto na ye won pe;
Kristi ngb’ awon elese.

2 f Wa ,y;o fun o ni ‘simi ;


Ggbagbo ‘oro Re daju,
Y’o gba ewni buru ju,
Kristi ngb’ awon elese.

3 cr Okan mi da mi lare,
Mo mo niwaju ofin;
Eni t’ we mi mo,
Ti san gbogbo gbese mi,

4 f Kristi ngb’ awon else


An’ emi to kun f’ese
Mo ba wo joba orun,
Amin
399
10.10.10.7 &Ref.
E mase je ki okan yin daru. Jn. 14:
1
1. mf Are mu o, okan re po ruru
So fun Jesu, so fun Jesu:
Ibanuje dipo ayo fun o?
So fun Jesu nikan,
So fun Jesu, so fun Jesu,
On l’ore ti o mo;
Ko si ore
Tabi ‘yekan bi Re
So fun Jesu nikan.

2. mp Asun dekun omije lo nsun bi?


So fun Jesu, so fun Jesu,
Iwo l’ese ti enikan ko mo?
So fun Jesu nikan.

3. p Iwo nfoya ‘banuje ti mbe bi?


So fun Jesu, so fun Jesu
Iwo ns’aniyan ojo ola bi?
So fun Jesu nikan.

4. p Ironu iku nda o lamu bi?


So fun Jesu, so fun Jesu
O nsaferi ijoba Jesu bi?
So fun Jesu nikan.
Amin
400
10.6.10.6.&Ref.
Okan mi ti mura , Olorun okan mi ti mura,OD.57:7

1. mf Okan mi, a tun fi Jesu lo o


L’ekan si n’nu oro Re
Nisisiyi, Oluwa, un o pinnu
N ki o ha gba Tire?
Mo fe, mo fe
B’Olorun se ‘ranwo
Emi fe je Tire
Eje Re ‘yebiye lo fi ra mi,
Emi yo je Tire.

2. mf Nipa or’ofe l’em ‘o r’anu gba


Mo jere ife Re
Kristi iwo li emi o gbagbo
Un o si gbekele O.

3. mp Oluwa, iwo mo ailera mi


Bi nko ti fe sako
‘Wo nikan lo le fun ni l’agbara
Lati josin fun O.

4. Oluwa f’or’ofe fun wa loni


Ka le jumo korin
Ki gbogbo wa so tokantokan pe,
Emi yo je ti Kristi.

5. mf Awon to t’o o wa nigba aye Re


Lati toro ‘bukun
“Mo fe” ni idahun ti won ri gba
On na la gbokan le
. Amin
401
C.M & Ref.
E gba ajaga mi si orun nyin ti won eniyan o ri ismi fun okan nyin , Mat 11:29

1 mpWa, okan t’eru ese npa;


Alanu l’Oluwa;
cr Oun y’o si fun o n’isimi
Bi o ba gbeke le,
Sa gbeke le (2)
Gbeke le loni,
Y;o gba o la.(2)
Y’o gba o loni.

2 di N’tori Jesu ta eje Re,


Lati fun o l’ayo;
cr Wa n’oku ninu eje na,
Ti nso ni d’mimo,

3 mf Beni, Jesu l’oto, L’ona,


Yo f’isimi funO,
Gb’eke re le, ma jafara;
Wo o ri bukun gba,

4 f Wa,wo ‘nu egbe mimo yi,


Ka lo sinu ogo,
Lati gbe ilu mimo na,
Nibiti ayo ki tan,
Amin
402
8.8.8.6.&.Ref.
Ebo Olorun ni irobimuje okan.OD.51:17

1 mpOluwa mi,mo ke pe O,
Un o ku b’O ko ran mi lowo
Mu igbala Re to mi wa,
Gba mi bi mo ti ri
p Gba mi bi mo ti ri(2)
Kristi ku fun mi l’ebe mi
Gba mi bi mo ti ri.

2 pp Mo s’ ailokun,ebi mi po;
O ta ‘je Re sile fun mi ;
O le se mi b’o ba ti fe,
Gba mi bi mo ti ri.

3 p Ko si ohun ti mo le se.
Nko le duro ti pinnu mi;
cr Jo, gba mi n’tori oko Rre.
Gba mi bi mo ti ri

4 p Wo mi, mo wole l’ese Re.


Se mi b’o ti to loju Re.
Se ise Re l’ase pari.
Gbami bi mo ti ri
Amin
403
8.6.8.6.6.6.&Ref.
Nitori oro Olorun ye o si li agbara Heb.4:12

1 mpE tun won ko fun mi, ki ngbo


Oro ‘yanu t’iye;
Je ki ntubo gbadun won si
Oro ‘yanu t’iye,
mf Oro iye didun,
Ti nko ni ‘gbagbo,
cr Oro didun , oro ‘yanu
f Oro ‘yanu t’iye.

2 f Krist’ Olubukun ti fun wa,


Oro ‘yanu t’iye
Elese gbo ‘pe ife na,
Oro ‘yanu t’iye;
L’ofe la fi fun wa.
O si nto wa s’orun.

3 f Gbe ohun ihinrere na.


Oro ‘yanu t’iye.
Fi ‘dariji lo gbogb’ eda.
Oro ‘yanu t’iye
Jesu Olugbala,
So wa di mimo lae.
Amin
404
7.6.7.6.D.&.Ref.
Oro re ti dun mo mi li enu to OD.119:103

1 mf ‘Wo oro dun julo


To kun ileri
Ati imuse pelu.
Opin ohun ‘jinle
p Nigba ekun at’ ayo,
di Yemeji at’ eru;
p Mo gbo Jesu wipe wa
Mo si lo s’odo Re.
f Wa, wa s’odo Re.
Wa, wa s’odo mi,
Aare t’orun nwo
Wa, wa s’odo mi,

2 mpOkan mi, wo yo se lo.


Kuro lod’ore yi,
Sa sunmo timotimo;
Ba gbe titi d’opin ;
p O se ailera mi po;
Mo kun f’ese pupo.
N’tor’ emi ko le sako;
Lehin mo ba pada.

3 mpMa mu mi sunmo ‘do Re,


Ki wa ‘na ba le je
Ohun ti a fo jeje
F’eni t’o sunmo O,
Mo mbe l’oke tab’ odo,
L’okere nitosi
Emi o ma tele O,
Gba mo ba pe, wa’
Amin
405
8.7.8.7.& Ref
Emi wa pelu nyin nigbagbogbo , Mat.28;20

1 . Onisegun nla wa nihin,


Jesu abanidaro
Oro Re mu ni l’ara da,
A gbo ohun ti Jesu
f Iro didun l’ori Seraf
Oruko didun li ahon
Orin to dun julo ni;
di Jesu, Jesu, Jesu.

2. mp A fi gbo gb’ese re ji O
A gbo ohun ti Jesu
cr Rin lo s’orun l’lafia
Si ba Jesu de ade.

3. f Gbogb’ogo fun Krist’ t’ojinde


Mo gbagbo nisisiyi
Mo f’oruko olugbala
Mo fe oruko Jesu.

4. Oruko Re l’eru mi lo
Ko si oruko miran
B’okan mi ti nfe lati gbo
Oruko Re ‘yebiye.

5. f Arakunrin, e a mi yin
E yin oruko Jesu
Arabinrin, gb’ohun soke,
E yin oruko Jesu.

6. Omode at’agbalagba
T’o fe oruko Jesu
Le gba pe ‘fe nisisiyi
Lati sise fun Jesu.

7. Nigbat’a ba side orun


Ti a ba si ri Jesu;
A o ko ‘rin yi ‘te ife ka,
Orin oruko Jesu.
Amin
406
C.M
Emi ni Olorun Olodunmare; ma rin niwaju mi,ki iwo ki o si pe Gen.17:1

1 mpKi n’ireti ipe wa je.


Leyin iwa-mimo?
Fun eyi ni mo nwo Jesu,
Ti mo si duro Je.

2 cr Mo duro, tit’ On yo we mi,


Ti yo f’iye fun mi,
At’ igbagbo ti nle ese,
Ti nso kan di mimo.

3 mf Or’ofe rapada l’eyi,


Ofe ni f’else;
Loto yo se lori emi
Olori elese,

4 p On yo ra okan mi pada ,
Kuro n’nu gbogb’ ese
Mo gba Jesu gbo nitoto
Mo fi ara mi fun.

5 mpNigba Jesu ba nbe’nu mi,


Gba mi lowo ese,
Okan mi nfe lati gba O,
Wole,Olugbala mi.
Amin
407
12.8.12.8.&Ref
Bi enikan ba wa ninu Kristi ,o di eda titun,IIKro 5:17

1. f Iyipada ‘yanu l’aye mi lati se


‘Gba Jesu wonu okan mi;
ff Imole nla ti de ti mo ti nwa kiri
‘Gba Jesu wonu okan mi
f Gba Jesu wonu (wonu) okan mi
Gba Jesu wonu (wonu) okan mi
Odo ayo nsan l’okan mi b’igbi okun
‘Gba Jesu wonu okan mi.

2. mpMo ti f’opin si ‘rinkiri ati ‘sina,


‘Gba Jesu wonu okan mi;
Ese mi to si po lati fonu kuro,
Gba Jesu wonu okan mi.

3 mfMo ni ‘reti kan to ni idaniloju,


Gba Jesu wonu okan mi;
Ko sohun to le mu mi siyemeji mo
‘Gba Jesu wonu okan mi.

4. f Emi yo si ma gbe ni’lu na ti mo mo


‘Gba Jesu wonu okan mi;
Inu mi ndun, mo si nyo bi mo ti nlo
‘Gba Jesu wonu okan mi.
Amin
408
10.11.10.8.D.
Jesu si wa fun u pe , Riran; igbala re gba o la Lk 18:42

1 cr Afoju agbe na, wa leba ona,


Titi Jesu fi wa , to wa s’ona
f Inu re si dun s’agbara Olorun,
‘Gba Jesu gb’ona koja.
cr Ebi on ese njoba laye mi,
Ki Jesu ko to gba ona mi koja;
mf Nisisiyi ayo at’ alafia de,

2 f Gbolohun kan lat’ enu Oluwa


Lo l’agbe na loju, gba Jesu nkoja;
Igbagbo agbe na nin’ oro na,
Fi imole kun okan re,

3 f Mo gbo iro didun ti angeli,


Gba Jesu nkoja to ngb’ ona mi koja ;
Bi won ti nf’ ayo korin ‘rapada
‘Gba Jesu ngb’ ona mi koja.

4 mf Else wa sodo Olugbala ,


Ka we o nu kuro ninu ese re,
Jeki mole Oluwa wonu re,
Gba Jesu gb’ona yen koja,
Amin
409
11.11.11.11.10.9.11.11.&.Ref
Awa o tun nkan yi gbo li enu re, Ise A. 17:32

1 mpSo fun wa b’o ti se gba idariji;


Awa tun nfe gbo itan na lekan si,
Bo se wa sib’ agbelebu fun ‘gbala,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si,
O ha bo n’nu mole ibukun Re?
O ha bo ninu ebi gbogbo?
mf Krisat’ ba je ayo, orin re n’gbagbogbo?
Awa tun nfe gbo itan na lekan si,
mf Jjo,tun itan na so fun wa,
Jo,tun itan na so fun wa lekan si
Tun itan na so fun wa ,
Jo, tun itan so fun wa lekan si
f Itan didun ti ibukun ,
Yio ran o lowo de ogo,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si,

2 mf So fun wa Jesu ha mba o sise bi?


Awa tun nfe gbo itan na lekan si,
So fun wa O ha ngbe o li apa Re.
Awa tun nfe gbo itan na lekan si,
Ko tun si ore, ti o dabi Re,
To le mu o la isoro ja,
f Jek’ araye gbo ohun t;o se fun O,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si.

3 mf O ha ti korin ,bukun bi eyi ri?


Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
f Orin ti o dun ju ala didun lo,
Awa tun nfegbo itan na lekan si;
Opo lo ti nwa isimi kiri,
T’ibajujegori okan won
f Kede Jesu fun won l’oro tab’ orin
Awa tun nfe gbo itan na lekan si,

4 mpSo ijakadi re at’ isegun re,


Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
Yo ran awon to se sese gbagbo lowo,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
cr Ogun orun apadi la mba ja,
Laipe a o ba Jesu joba,
Eyin ta ra pada, e mu eso wa,
Awa tun nfe ita na lekan si’
Amin
410
11.10.11.11.&.Ref
Osje ki o mu oyin lati apata wa,Deut 32:13

1 p Nin’ aginju ese, Jesu wa mi ri,


Ninu ogbun ese ainireti ;
Jeje lona iariji l’o nto mi,
O si nfi onije bo mi li aginju,
mf Pel’oyin n’apata to lo fi mbo awon Tire ,
Oyin didun lati nu’ apata,
Pel’oyin n’apata ‘l’ofi mbo awon Tire.
Didun l’ebun Olorun.

2 f Ninu oro ore-ofe nfun mi


Ni, bukun ‘yanu lo mayo mi kun.
Jojumo lo nfi sura Re bokan mi,
Oyin , wara eso to daju.

3 ff A ko le so gbogb’ ayo ti rapada,


A ko le so gbogb’ ayo ti rapada,
` A ko le so darij’ aura bukun
A ko le so won ‘bukun to wa n’nu nini
Imo’ dariji at’ laelae.

4mp Wa elese ipe nla eyi je,


Wa pel’’ okan re t’eru ese npa,
Ki o ba le ni ipin ninu ayo
Ta se leri re fun awon oloto.
Amin
411
7.7.7..7.7.7
A ko fi ohun ti idibaje ra nyin pada bifose eje Jesu.Ipet,1:18:19

1 mf Jesu f’eje Re ra wa,


E jek’a sunm’ Olorun ;
Opo nsina yi wa ka,
di K’anu mu wa gbadura,
Pe ki won t’o fo ‘ju
Laipe le r’ ona oto,

2 mf Oluwa ,ji won yika ,


Ki won mo pe ayo na.
Eru esu leekan ri,
di Oluwa , awa nwo O,
D’elese ‘gbekun sile,

3 mf Agbo’royin ogo Re.


Ohun t’apa Re ti se,
Opo so t;ipa Re.
f A ba tun le ri sa ni.
Mu won soji Oluwa ;
Ipa iyin na Tire .
Amin
412
C.M
Yaralatiran mi lowo Oluwa igbala mi,OD 38:22

1 mpWa ,Oluwa l’anu tun wa,


Pelu ‘pa p’okan da,
Onigbe ojo np’oko Sion,
Masai ro s’ ori re,

2 p Okan wa kun f’are kikan,


Lati ri b’elese,
Ti airi iranwo,

3 p ‘Jesu , wa pelu ‘pa ‘soji’


L’eeyan Re nke
Mu ‘gbala wa ni sa anu ,
Ma jek’ elese ku.

4 mf Jek’ elese ro s’ile Re.


Ki won ho isegun,
cr Gbana l’edun wa y’o d’ayo
Ekun ,d’orin iyin.
Amin.
413
L.M
On o si fun nyin ni olutunu miran,Jn, 14:16

1 mp Gbo l’or’ ite Re ,Alade


F’ oniruru’bukun ranse
B’won omo Re ti nwa O,
Gb’ adura t’oro Re ko ni,

2 mpWa, Emi Mimo lat’ oke


Fife kun okuta d’ tutu’
A s’okan okuta d’eran
K’o jek’ ipa Re di mimo

3 p Soro ,oju t’o da yio sun


Ekun ‘robinuje jade,
Won yo si figbona okan
Wa ore rti won ko nani

4 mf A jek’opo awon mimo


Duro n’ilekun Re.
di K’olukulu se tara
Lati f’ara rubo funo,
Amin
414
L.M
Bi enikan ba gbo ohun mi, ti o si si ilekun ,emi o si wole to o wa,Ifi3:20

1 mf Ara n’nu krist’ nirtori Re.


A fi t’okantokan gba o,
K’a le jumo je ayo ti.
Ko s’en;ti fun ni lehin Re.

2 K’Enit’ a pe nipa ‘ke Re.


p Ran Emi re Re sokale
K’O jeki ede wa k’o dun
K’okan wa gbona fun ife

3 Gb’ onigbagbo ba pe bayi,


Ero aye a d’igbagbe;
A nfe lati s’oro en’t’o
Ku, t’O joba wa nikan

4 p Ao,so t’ ise at’ oro Re.


T’iya t’o je fun wa l’aye;
T’ona t’I la fun ririn wa,
T’ohun t’o nse l’owo fun wa.

5 mf Bi akoko ti nrekoja,
Ao feran ao sin n’iyanu
Ma reti ojo ogo ni
Ti ao pe li aipinya mo,
Amin
415
7.7.7.7.
Olorun re ni yio ma se Olorun mi, Rutu 1:16

1 mpEyin eeyan Olorun,


Mo ti kiri aye ka,
To’ pa ese on ‘kanu
Nko r’itunu n’ibikan,

2 Okan mi pada si yin,


Emi isansa,mo de
Nibi pepe yin ba njo
E,jo gba mi s’ismi.

3 Emi k’yo nikan rin mo,


Bi ategun at’ igbi;
‘Bugbe yin yo je le mi,
‘Busun yin , iboji mi,

4 f T’emi ni Olorun yin,


Jesu yin yio je t’emi;
Aye kole tun fa mi,
Mo ko gbogb’ osa sile
Amin
416
C.M
E mse fe aiye, I Jn. 2:15

1 mf Awa fe ohun aye yi,


Won dara l’oju wa;
A fe k’a duro pe titi,
Laifi won sile lo,

2 Nitori kini a nse bee?


Aye kan wa loke
Nibe l’ese on buburu
Ati ewu ko si

3 Aye t;’o wa loke orun,


Awa iba je mo
Ayo,ife,inu rere,
Gbogbio re wa nibe,

4 p Iku, o wa ni aye yi,


Ko si loke orun;
Eniyan Olorun wa mbe
Ni aye ,ni aiku

5 K’a ba ona ti Jesu lo,


Eyi t’O la fun wa.
ff Sibi rere ,sibi ‘simi
cr S’ile Olorun wa.
Amin
417
11.11.11.6.&Ref
Bikosepe a tun eniyan bi, oun ko le ri ijoba Olorun John 3:3.

1. mfIjoye kan to Jesu wa li ale,


Lati bere ona ‘gbala on ‘mole,
Olukoni dahun l’oro oto pe,
mpA o le saitun yin bi,
cr A o le saitun yin bi (2ice),
Otito li oro na ti mo so pe,
cr A o le sai tun yin bi.

2. mp Eyin omo eniyan, e gbo oro,


Ti Jesu Oluwa so pelu edun
Ma se je k’oroo na bo s’asan fun yin,
A o le sai tun yin bi.

3. mpEyin te nfe de ‘bi simi ogo yi,


Lati ba awon mimo korin ‘bukun,
Bi e ba fe gba iye ainipekun,
A o le sai tun yin bi.

4. mpOlufe t’okan re nsaferi jojo,


Le ma w’ona re ni ibode orun;
Nje fetisi ohun orin jeje yi;
p A o le sai tun yin bi.
Amin
418
12.12.12.6.D
Emi o sibere lowo Baba ,on O si fun yin li olutunu miran Jn.14:16

1 `f Tan ihin na kale ,jakejado aye,


K’awon ti eru npa ,mo pe igbala de’
mf K’awon ti se ti krist’,so ihin ayo na.
Olutunu ti de,
mf Olutunu ti de,Olutunu ti de ,
Emi lat’ oke wa ,ileri Baba wa’
f Tan ihin wa, kale jakejado aye
Olutunu ti de.

2 mf Oba awon oba,wa f’iwosan fun wa.


O wa ja ide wa,O mu igbala wa,
K’olukuklu wa. Korin isegun pe,
Olutunu ti de.

3 ff Ife iyanu nla, a mba le royin na.


Fun gbogbo eniyan ,ebun or’ofe Re.
f Emi omo egbe, di omo igbala,
Olutunu ti de.

4 f Gbe orin yin soke s’Olurapada


K’awon mimo loke ,jumo ba won gberin
ff Yin ife Re titi, ife ti ko le ku,
Olutunu ti de.
Amin
419
L.M
Nwon o ma soro ogo ijoba Re nwon o si ma soro agbara Re. OD 145:11

1 mf Emi anu oto, ife


Ran agbara Re toke wa,
cr Mu iyanu ojo oni
De opin akoko gbogbo

2 f Ki gbogbo orile ede


Ko orin ogo Olorun
Ki a ko gbogbo aye
N’ise Olurapada wa.

3 mp Olutunu at’ Amona,


cr Joba ijo Eniyan Re.
mf K’araye mo ibuklun Re.
Emi anu ,oto ife
Amin
420
7.7.7.7.D
Oluwa,Olorun Olodunmare njoba ifi.19:6

1 f Gbo orin ti Jubeli’


O dabi sisanara’
Tabi bi kikun okun
‘Gbat’ igbi re ba nlu ‘le ‘
ff Aleluya Olorun
Olodunmare joba
ff Aleluya k’oro na
Dun yi gbogbo aye ka.

2 f Aleluya gbo iro’


Lati aye de orun
Nji orin gbogbo eda,
L’oke,nisale yika,
Wo Jehofa ti sete,
p Ida e’ako’ O pase
Awon ijoba aye
Di ijoba Omo Re.

3 Yo joba yi aye ka,


Pelu agbara nlanla ;
Yo joba ‘gba orun
At’ ayeba koja lo;
p Opin de lab opa Re.
pp L’ota eniyan subu ;
ff Aleluya Olorun
Ni gbogbo l’ohun
Amin
421
7.6.7.6.D
Lojojumo li a o si ma yin Lod.72:15

1 f Alafia un Jesu
Omo nla Dafidi;
Ni akoko ti a yan
N’ijoba Re bere;
mf O de lati tan iya.
Lati tu igbekun,
Lati mu ese kuro
Yo joba l’aisegbe.

2 mf O mbo wa pelu ‘ranwo ‘


Fun awon ti njiya,
Yo ran alainilowo.
Yo gb’ alailera ro’
cr Yo f’orin dipo ose.
Okun yo di mole
F’okan ebi ti nku lo,
To s’owo loju Re.

3 mpYos’ okale bi bi ojo


Sori ile aye.
Ife ayo ireti,
So jade l’ona Re.’
mf Alafia yo kede Re.
Lori awon oke
Ododo b’isun omi.
Yo toke san sile.

4 di Arb’ alarinkiri,
Yio wole fun U’
Alejo etiopea
Yiop wa w’ogo Re.
mf Oko okun o pade
Lati f’isura okun
Josin lab’ese Re.

5 mpOba yio wole fun


T’awon ti turai
Gbogbo orile ede
Yo korin iyin Re.
mf Lojojumo l’adura
Yio ma goke lo,
Ijoba Re yo gb’ ile
Ijoba ailopin

6 f Yo segun gbogbo ota.


Yo joko n’ite Re,.
Ogo Re yin ma ran.
Alabukun laelae
mf Ayida aye ko le.
Ife li oruko pada laelae.
Amin
422
L.M
Ji,ji ,gbe agbara wo, iwo apa Olorun Isa 51:9

1 f Ji apa Olorun ko ji,


Gbe ‘pa wo ,mi orile
Ni sisan Re,jek’aye ri
Isegun ise anu Re.

2 ff T’ite Re wi fun keferi,


Emi Jehofa Olorun
Ohun Re yo d’ede won ru’
Yio wo pepe won lule.

3 mf Ki gb’ ojurere Sion ‘de


ka m’ eya ireal’wa ru
N’iyanu ka f’oju wa ri,
Kferi ,ju l’agbo Jesu

4 f Olugbala kede ;fe ‘fe Re


L orile ede gbogbo;
Ki gbogb’ ota wole fun O,
Ki won gba Jesu l’Oluwa.
Amin
423
7.6.7.6.D
Wa ki o si wa lowo iswe A.16:9

1 mf Lat’ oke tutu Grinland


Lati okun India
Nib’ odo orun Afrik
Nsan ‘yanrin wura won.
Lat’ opo odo ‘gbani
Lati igbe ope
Won npe wa k;’gba le won,
L’ewon isina won.

2 Afefe orun didun,


Nfe je ni Sriilanka
Bi ohun ta nri dara,
di Eniyan lo buru;
mpLasan, lasan l’Olorun,
Keferi ni foju gbogbo ka,
Nwole bo okuta.

3 mpNje awa ti a mole


Nipa ogbon orun.
O to ka f’imole du
Awon to wa l’okun
ff Igbala A igbala
Fonrere ayo na
Titi gbogbo orile
Yoo mo Messiah.

4 f Efufu, mu ‘hin re lo,


Ati eyin odo,
Titi bi okun ogo
Yo tan yi aye ka
Tit’ Odagutan ta pa
Fun irapada wa
ff Yio pada wa joba.
Lalafia laelae
Amin
424
L.M
Wasu oro na.ll Tim 4:2

1 mf Keferi nasegbe l’ojojo


Egbegberun lo nkoja lo,
f Mura kristian s’igbala s’igbala won.
Wsu fun won ,ki won to ka,

2 f E yonda owo ,at’ ebun


At’ emi yin ,ki le ye;
Jesu se ohunnla fun yin.
Kil’ ohun te ki o se fun.

3 Emi Oluwa ,fo kiri,


Jakejado ile aye,
Lati jakejadi aye
Ko awon om’Olorun jo
Lati gbogbo oril’-ede
Amin
425
L.M
E ma po si ni ise Oluwa nigba gbogbo lkro15:58

1 f Ma sise lo,Baba re,


Fi ayo sise Baba re,
Bayi ni Jesu se l’aye
Ko ha ye k’awa ko se be.

2 Ma sise lo ki se lasan,
Ofo aye l’ere orun ;
Bi araye ko fe yin o,
Iyin Jesu ju t’eda lo,

3 f Ma sise, l’ojojumo,
p Okunkun aye fere de,
f Ko ba le gba okan rer la,

4 p Pupo, pupo l’awon to ku,


Ti wobn ko n’ireti orun
Gbe ina ‘bagbo re ma fi
Ma fi si okunkun aye.

5 Ma sise lo, gbadura ;


F’ogbon wa awon to sina
Jade lo s’opopo ona.
Ro asako lati wole

6 f Ma sise lo, ma yo pelu


Lehin ise ‘wo o simi;
O fere ‘gb’ ohun Jesu na,
ff Y’o ke tantan pe , ‘Emi de’
Amin
426
6.6.4.6.6.6.4
Olorun si wipe, Je ki imole ki o wa, imole si wa Gen. 1:3

1. f Iwo ti okunkun
Gb’oro agbara re
cr To si fo lo:
p Gbo ti wa, a nbe o
Nibit’ ihinrere
Ko ti tan mole re
f K’imole wa.

2. mf‘Wo t’iye apa Re


Mu iriran w’aye
cr At’ilera
p Ilera ti inu
Iriran ti okan
Fun gbogbo eniyan
f K’imole wa.

3. mpIwo Emi oto,


Ti o n f’iye fun wa
cr Fo kakiri
Gbe fitila anu
p Fo ka oju omi,
Ni ‘bi okunkun nla
f K’imole wa.

4. f Metalokan Mimo
Ogbon, ife, ipa,
Alabukun!
ff B’igbi omi okun
Ti nyi ni ipa re,
Be ka gbogbo aye
K’imole wa.
Amin
427
11.11.11.11
Olorun tikarare si wa pelu wa li Olori wa llkro 13:12

1 ff Gbo iro efufu lat’ ‘ona jinjin,


O nsoro ‘jakadi ti ogun mimo’
Olorun mbe fun wa, O ti soro Re.
O si nso gbogbo yin,Ojise orun.

2 mf Lo’wo ihinrere ,ma segun titi;


Okukun ndimole ni gbogbo aye.
O sa wole fun O, ile won si wo
Gbogb ‘eda bu jewo pe ‘Wo ;’Oluwa

3 f Olugbala mimo ti njoba loke,


K’awon om’ ogun Re ma ri O titi.
Je k’oro Re ma tan lat’ ile de le
Ki gbogbo agbaye teriba fun O,
Amin
428
6.6.6.6
Ki ijoba Re de.Mat 6:11

1. mf Krist’ ki ‘joba re de
Ki ase re bere
F’opa irin re fo
Gbogbo ipa ese.

2. p Ijoba ife da?


Ati t’alafia
‘Gba wo ni irira
Yio tan bi t’orun?

3. Akoko na ha da
T’ote yi o pari
Ika ati ‘reje
Pelu ifekufe.

4. mp Oluwa, jo dide,
Wa n’nu agbara Re;
Fi ayo fun awa
Ti o ns’aferi re.

5. p Eda ngan oko re


Koko nje agbo re
Iwa ‘tiju pupo
Nfihan pe ‘fe tutu.

6 . Okun bole sibe


Ni ile keferi
cr Dide ‘rawo oro;
ff Dide mase wo mo.
Amin
429
13.6.13.6.13.13.13.15.13.6.13.6
E wi larin awon keferi pe Oluwa l’Oluwajoba. OD.96:10

1 Wi jade larin keferi p’Oluwa l’Oba


Wi jade Wi jade
Wi jade f’orile-ede mu ki won korin,
Wi jade Wi jade.
cr Wi jade tiyin pe, On o ma po si,
Pe, Oba nla ologo l’Oba alafia,
ff Wi tayotayo bi iji tile nja.
Pe, O joko lor’ isan omi, Oba wa titi lae.

2 Wi jade larin keferi pe, Jesu n joba ,


Wi jade Wi jade.
cr Wi jade f’orile ede mu k’ide won ja.
Wi jade Wi jade
p Wi jade fun awon ti nsokun pe, Jesu ye.
Wi jade f’alare pe,O nfunisimi,’
Wi jade f’elese pe .O wa lati gbala.
Wi jade dfun awon ti nku pe, O ti segun iku,

3 f Wi jade larin keferi krist’ njoba Re,.


Wi jade Wi jade.
Wi jade fun keferi ife n’ijoba Re.
cr Wi jade l’ona opopo l’abuja ona
Je ko dun jakejado ni gbogbo agbaye,
ff B’iro omi pupo ni k’iho ayo wa je.
Titi gbohun yo fi gbe iro na de kanbun aye.
Amin
430
8.7.8.7
Nitori ni lati nitori ihinrere Mk.8:35

1 f Tori mi at’ ihinrere


E lo so’t’lrapada
cr Awon onse Re nke ‘Amin’
f Tire ni gbogbo ogo’
mf Nwon nso ‘ ibi t’t’iya t’iku
Ife etutu nla Re.
Nwon ka ohun aye s’ofo
f T’ajinde on joba Re.

2 f Gbo, ipe ji Jubeli,


O ndun yi gbogb’ aye ka,
cr N’ile ati l’oju okun,
A ntan ihin igbala
p Bi ojo na ti nsunmole
T’Ogun si ngbona janjan
f Imole ila –orun na
Yo mo larin okunkun.

2 f Gbo,gbo ipe ti Jubeli ,


O ndun yi gbogb’ aye ka
f N’ile ati l’oju okun
A ntan ihin igbala;
p Bi ojo na ti nsunmole ,
T’ogun si ngbona janjan,
f Imole ila orun na
Yo mo larin okunkun,

3 f Siwaju ati siwaju


Lao ma gbo’Aleluya
cr Ijo Ajagun yo ma yo
Pel’awon oku mimo
A foaso won n’nu eje
Duru wura won si ndun ,
ff Aye at’ orun d’ohun po,
Won nko orin isegun.

4 f O de Eni t’a nwona Re.


Eni ikehin na Re.
Imanueli ti Oo de ‘ade
Oluwa awon mimo,
cr Iye , Imole at’ titi lae,
Metalokan titi lae.
ff Tire ni ite Olorun
Ati t’odo Agutan.
Amin
431
L.M
O n o joba lat’ okun de okun OD.72:8

1 f Jesu yo joba ni gbogbo


Ibit’ a ba le ri orun
‘Joba Re yo tan kikairi
‘Joba Re ki o nipekun

2 mf On li ao ma gbadura si,
Awon oba yo pe l’Oba.
Oruko Re b’orun didun
Y’o ba ebo oro g’oke

3 Gbogbo oniruru ede


Yo fi Re korin didun
p Awon omode yo jewo ,
Pe’bukun won t’odo Re wa.

4 f ‘Bukun po nibi t’On joba


A tu awon onde sile.
Awon alare ri’simi,
Alanini s’ri’ ‘bukun gba.

5 ff Ki gbogbo eda ko dide


Ki won f’Ola fun Oba wa,
K’angeli tun wa t’awon t’orin
Ki gbogb’ aye jumo gberin.
Amin
432
6.6.6.6.8.8
O ti ran mi lati kede idasile fun awon igbekun. Isaiah 61:1

1 f E fun ‘pe na kikan,


Ipe ihinrere:
K’o dun jake jado
L’eti gbogbo eda,
ff Odun idasile ti de
Pada elese, e pada.

2. Jesu Alufa wa
Ti s’etu lasepe
Alare, e simi,
Asofo tujuka.

3. mf Fun ‘pe t’od’agutan


Ta ti pa setutu
cr Je ki agbaye mo
Agbara eje Re.

4. Eyin eru ese


E so ra yin d’omo
Lowo Kristi Jesu
E gb’ominira yin.

5. f Gbo ‘pe ihinrere


Ihin ore-ofe
Agba yin low’aye
E wa ‘waju Jesu.
Amin
433
L.M
Emi yio tu ninu Emi mi sara eniyan gbogboIse A.2:17

1 f Emi Olorun alaye,


N’nu ekun ore-ofe Re,
Nibit’ ese eeyan ti te,
Sokale s’ori iran wa,

2 mf F’ebun ahon,okan ife


Fun wa,lati soro fe Re,
K’ibukun at’ agbara Re,
Ba l’awon to ngbo oro na,

3 K’okun ka ‘se ni bibo Re,


Ki daru dapo di tito’
F;ilera f’okan ailera,
Je anu bori binu,

4 mp Emi Olorun,jo pese


Gbogbo aye fun Oluwa
cr Mi si won b’afefe oro,
K’okan okuta je soji,

5 f Baptis’gbogb’orile-ede,
Royin segun Jesu yika’
Yin oruko Jesu l’ogo’
Tit’araye yo jewo RE,
Amin
434
8.8.8.6.&.Ref
E ji iji ododo Ikro 15:34

1 f Ji so sagbara Re d’otun
Gbe ‘hamora ogun ota
A o segun gbogbo ota,
Kriasti yo si joba,
ff Krist’ y’o joba
Krist’ y’o joba
Ireti wa n’nu Re ko ye’
Krist’ y’o joba
Krist’ y’o joba
Krist’ y’o joba
Ireti wa n’nu Re ko ye.
Krist’ y’o joba,

2 mp O ti pe t’awon omo Re.


Ti nse yapa lori eko;
Won gbagbe pe l’ori sokan
Ni On lo aye Re.

3 mf E papo li agbararE.
Aye yin yo si je ere;
f Laipe e o ni isegun
Tori krist’ y’o joba,

4 cr O ye ka sise F’Oluwa
Ise wa ko ni je asan
mf A ko gbodo pada s’ehin,
Tori krist’ y;o joba.
Amin
435
7.6.7.6.D
Kristi si ni ori Ijo Re Efe 5:23

1 f Jesu Oluwa ni ‘se


Ipinle Ijo Re.
Omi ati oroRe
Ni On si fi tun de’
O t’orun wa, o fi se.
Iyawo mimo Re
mp Eje Re lo si fi se;
p Ti O si ku fun wa

2 Nile gbogbo la sa won,


Subon won je okan;
Oluwa kan gbogbo kan
Ati baptisi kan;
f Oruko kan ni won yin,,
Onje kan ni won nje,
Opin kan ni won nlepa,
Nipa ore ofe,

3 Bi aye tile nkegan ,


‘Gbati iyonu deba,
B’ijaon eko keko
Ba mu mimo yo ma ke
Awon mimo yo ma ke
f Wipe ‘yo ti pe to?
Oru ekun fere di
Oro orin ayo,

4 di L’arin gbogbo ‘banuje


At’ iyonu aye’
O nreti ojo ‘kehin
Alafia laelae;
Titi yo f’oju Re ri
Iran ologona,
Ti d’ijo ti nsimi.

5 mf L’aye yi o ni dapo
Pelu Metalokan;
O si ni dapo didun
Pel’awon to ti tun;
f A alabukun mimo
Oluwa fi fun wa,
Ka ba le ri bi awon,
Ka ba O gbe l’orun
Amin
436
D.C.M
Ki ife ara ki o wa titi Heb, 13:1

1 f Olugbala o f’ayo han


Ki gbogb’ aye le ri,
Ayo’ simi, alafia
T’awon to fe O ni,
mf Gbogbo aye gbogbo aye,
Gbogbo, tile,t’okun (toke),
A fe gbogbo aye fun krist;
K’o rile d’ominira,

2 mf Je ka le soro hinrere
Titi gbogb’okan wa
Pelu gbogb’ eni yi wa ka,
Y;o fi gba O l’ba,

3 f Ran wa b’ ina at’orun wa,


Ti mole re yo tan,
Tit’awon to wa n’nu okukun
Yo ri imole na,

4 mf Je ki ‘yanu or’ofe Re
Kun inu okan wa,
K’awa le fi itara lo,
Lati se ‘ranwlowo
Amin
437
7.7.7.7
Oluwa joba ki aye ki o yo OD.97:1

1 mf Oluwa joba aye


Korin ‘yin eyin eda;
E korin tayo-tayo,
Jesu Messiah joba

2 f Jesu la f’agbara fun


Oluwa gbogbo aye,
Eru, gbo k’owairi

3 ff K’awon angeli d’ohun po,


Ki won pe ajoyoyo na,
Ki won jumo yin Jesu
Ki won kede ‘segun Re.

4 mf B’omo okunkun sata,


Awon tiwa ju won lo,
Olorun mbe ko si nikan
Kristi mbe k’ota damu

5 f E f’oju igbagbo wo,


B’awon oke ti mole ;
Olorun mbe nitosi
O fi ‘mole yi wa ka/

6 mf Olugbala sokale;
O ntoka s’ade segun
O npe wa sipo loke,
O fe wa j’asegun lo,
Amin
438
7.6.7.6.7.7.7.6
Eni nla ni Oluwa ,OD.43:1

1 f Eni nla l’Olugbala


Ninu olanla RE,
On l’awon torun ajuba,
Ijo Re l’aye nyin;
Ni ilu Olorun WA.
Loke mimo Re k’aye
mf Kede oko Re k’aye
Fi titobi Re han.

2 cr Nitor’ isegun ife Re,


A duro n’ile Re
Nihin f’oto ‘fe Re han.
F’ipa gbala Re han;
A mo ‘yin Re l’oko Re,
Pipe ewa Re logo’
mp Gbogbo aye yo jewo
Pe ,mimo a ise Re.

3 mf Ijo Re mbe lailewu


O duro l’apata
Gbogbo leri re daju;
Tani le si n’idi /
Kiyes’ awon ofin Re.
So f’awon ‘ran ti mbo .pe.
f Ijo na ko le baje,
Lagbara Oluwa.

4 f Tiwa l’Oluwa Sion,


A simi le ‘fe Re,
A mo p’O ndariji ni,
On y;o se Oluto wa,
Si Jerusalem titun;
mf On l’Eni t’ a simi le
Titi ayeraye ,
Amin
439
7.7.11.D.&Ref
Ma ja ija rere ti igbagbo, lTim 6:12

1 mf Gbe asia na soke


Si ma gbe lojojumo;
Titi gbogb’ agbara ibi yo wole
f Jeki o ma fe lele
Pelu ‘hin krist’ le gbala;
Gbe soke titi yo fi yi aye ka,
Titi agbara nla ibi yio fi wo’
Pelu ‘hin krist’ le gbala’
Gbe soke titi yo fi yi aye ka’

2 mf Gbe asia,na soke


Ni gbogb’orile ede
Ki a ma se la asia na kuro,
f Titi aye yo korin
T’lmanueli, Oba won
Gbe soke titi yo fi yi ka,

3 mf Gbe asia na soke,


Ko ma dan ni gbogbo le,
M’ojo na yara de t;yo ma fe lele.
cr Mu fo,lat’ okun d’okun
Tit’ aye gba krist’
Gbe soke titi fi yi aye ka,
Amin
440
S.M
Awa ti ri irawo ri re ni iha ilu orun

1 f Irawo wo l’eyi
Wo b’o ti dara to’
Amona awon keferi’
S’odo Oba ogo.

2 Wo awon amoye
Ti ila orun wa,
Won wa fi ori bale fun,
Jesu Olubukun,

3 Imole ti Emi
p Ma sai tan ilu wa
Fi ona han wa k’a le to;
Imanueli wa,

4 f Gbogbo irun male.


Ati igba male
Ti a mbo n’ile keferi,
K’o yago fun Jesu.

5 mf Ki gbogbo abore
Ti mbe ni Alfrika,
Je amoye li otito,
Ki won gb’ebo Jesu

6 Baba Eleda wa,


Ti o fi Jesu han
Awon keferi igbani;
Fi han fun wa pelu.
Amin
441
6.6.6.6.8.8
Yio si joba ni ile jakobu titi aiye Lk.1:33

1 f E yo Jesu joba
‘Nu omo eniyan
O da ara tubu
O so won d’ominra’
K’esu koju s’Om’Olorun,
Lai f’ota pe ,ise Re nlo,

2 mf Ise ti ododo
Oro, alafia
Fun rorun aye wa,
Yio tan ka kiri
Keferi, Ju won o wole
Won o jeje isin yiye

3 f Agbara l’owo Re.


Fun abo eni Re
Si ase giga Re.
L’opo o kiyesi
Orun aye ri ise Re
Ekusu rere gb’ofin Re.

4 Irugbin t’orun yi
O fere d’igi nla’
Abukun wukara
Ko le saitan kiri
ff Tit’Olorun omo tun wa.
Ko le sailo, Amin, Amin
Amin
442
7s.6s.D
Nigbati oko iyawo pe, gbogbo nwon togbe ,nwon si sun.Mat 25:5

1 mf Oluwa y’o ti pe to
Ti ‘Wo o tun pada;
Are fere mu wa tan,
Bi a ti nw’ona Re;
Oluwa y’o ti pe to
Ta o ma reti Re
Opo ni ko gbagbo mo
Pe ‘Wo o tun pad,

2 Oluwa y’o ti pe to
Ti ‘Wo p kesi wa!
Ti awa ti nreti Re
Yio ri O l’ayo
Ji, wundia ti o sun
Lo kede bibo Re
Ki gbogbo awon t’o sun
Le mo pe O mbo wa

3 f Dide, tan fitilla re


Gbe ewu momo wo,
Mura lati pade Re
‘Tori On fere de
Oluwa y’o ti pe to
Ti ‘Wo o tun pada
Ma je ki are mu wa
Tit’ ao fi ri O.
Amin.
443
14.8s.
Iwo o fi imo Re to mi li ona, nigbakehin Iwo o gba mi sinu ogo. OD. 73:24

1 Olorun mi b’ojuwo mi
F’iyanu ‘fe nla Re han mi
Ma je ki ngbero fun ‘ra mi
‘Tori ‘Wo ni ngbero fun mi
Baba mi, to mi l’aye yi
Je ki ‘gbala Re to fun mi.

2 Ma je ki mbu le O lowo,
‘Tori Wo li onipin mi;
s’eyi ti ‘Wo ti pinnu re,
p Iba je ponju tab’ ogo.

3 Oluwa tal’o ridi Re


Iwo Olorun ologo?
Iwo l’egbegberun ona,
Nibi ti nko ni ‘kansoso,

4 B’orun ti ga ju aye lo
Beni’ ro Re ga ju t’emi;
Ma dari mi k’emi le lo
S’ipa ona ododo Re.
Amin
444
8.7.8.7..8.7
Imole lati si awon keferi Lk2:32

1 Wo gbogbo ile okunkun,


Wo okan mi, duro je;
Gbogbo ileri ni o nso
T’ojo ayo,t;o logo;
Ojo ayo, ojo ayo
K’owuro re yara de,

2 mf Ki gbogbo ile agbaye


K’alaigbede gbogbo ri,
Isegun nla t;o logo ni,
T’ori oke Kalfari
K’ihinrere k’ihnrere
Tan lat’ ilu de ilu,

3 Ijoba to wa l’okunkun,
Jesu,tan ‘mole fun won
Lat’ila –orun de ‘wo re
K’mole le okun lo
K’irapada k’irapada
Ti a gba l’ofe b’ori,

4 Ma tan lo, wo ihinrere,


Ma segun lo, ma duro ,
K’ ijoba re ayeraye
Ma bi si,ma re
Olugbala,Olugbala
Wa joba gbogbo aye.
Amin
445
7.6.7.6.D
Beli awa eniyan Re ati agutan papa Re yio
ma fi ope fun O lailai, awa o ma fi iyin Re h lati irandiran,OD.79:13

1 f Olorun igbala wa,


Emi at’ iye wa,
Ilera at’ abo wa,
At’ alafia wa,
Awa omo Re duro
Lati f’iyin fun O.
Fun ebun nla t;o fun wa,
Ninu kristi Jesu.

2 Okan wa kun fun ope


Fun ‘toju’gbagbogbo
L’ori awon omo Re
Ni gbogbo abaye.
mf Awa mbe O jek’awa
Le duro n’nu fe Re,
f K’imole wa le ma tan
Yi gbogbo aye ka,

3 ff Ogo f’Olorun Baba ,


At’ Olorun omo,
Pelu Olorun Emi,
Metalokan laelae
Jo gba orin iyin wa,
Ati adura wa
Fun ebun nla t’o fun wa,
Amin
446
L.M
E l0, e ma ko orile-ede gbogbo Mat.28:19

1 f Lo wasu ihinrere Mi
Mu gbogbo aye gb’ore Mi;
Eni t;o oro Mi y’o la;
Eni t’o koo yio segbe.

2 Emi o f’oye nla han yin,


E o f’oro oto Mi han;
Ni gbogbo ise ti mo se
Ni gbogbo ise t;o se

3 Lo wo arun,loj’oku nde
F’oruko Mi l’esu jade
Ki woli mi mase beru,
Bi Griki ati ju kegan,

4 Ko gbogbo aye l’ase Mi,


Mo wa lehin yin de opin;
Lowo mi ni gbogbo ipa,
Mo le pa , mo si le gbala;

5 Imole si ran yi ka ,
Ogo nla l’o fi lo s’orun;
Won si mu de ile jijin.
Ihin igoke Olorun.
Amin
447
O.t.H.C.127.8s.7s.
Ibi okunkun aiye,o kun fun ibugbe ika.OD.74:20

1 mf E fi oju iyonu wo,


Okun ile keferi;
Sa wo bi opolopo won
Ti njowere ‘nu ese,
p Okunkun bo,Okunkun bo,
Oju ile aye wa,

2 Imole eni okunkun,


Dide,mu ibukun wa
Imole f’;awon keferi
Wa,pelu’mularada;
Ki gbogb’ Oba ki gbogb’Oba
Wa sinu imole na,

3 Je k;awon keferi ti mbo


Igi ati okuta
Wa, lati fi ori bale
Fun Olorun alaye
Je k’ogo Re je k’ogo Re.
Bo gbogbo ile aye

4 f Iwo t’a fi pa gbogbo fun,


Soro na pa ase Re,
Jeki egbe Oniwasu
Tan ‘ruko Re ka kiri
Wa pelu won,wa pelu won
Oluwa titi d’opin
Amin
448
6s.4
Awon Oba Seba ti seba yio mu ebun wa OD.72:10

1 Lati erekusu
De ikangun okun
K’Oba juba Jesu.
Ki won mu ore wa,
Ki Arb’le
Orin orun;
K’Afrika dapo
Gbe yin Re ga

2 Om’alade y’o sin


Won o mu ore wa,
Lati yin agabara
Imanuel Oba
Ile jinjin
Yio josin
Ayer y’o gba
Ase Re gbo,
Amin
449
8.7.8.7
Oluwa wipe,wa nisisiyi,bi ese nyin ba ri bi ododo,nwon fun bi sno Isa,1:18

1 f Elese,wa sodo Jesu


Eni t;o wa gba o la;
Eni t;o gbe ara re wo,
Lati ru irora re,

2 Olodunmare ni Eni
T’o fi emi Re fun O,
Orun at’ aye y’o koja
Sugbon On wa titi lae

3 Ki ojo aye re to pin


p K’iku to p’oju re de;
f Yara, wa Olugbala re,
K’akoko na to koja

4 Gbo b’ohun Re ti nkepe o,


ff ‘Elese wa sodo Mi
ko eru na Mi wa
Gbagbo , reti ma beru’
Amin
450
8.7.8.7.7.7.7
Ma wi,Oluwa nitori iranse Re ngbo I sam 3:9

1 Ma wi,’tori ranse Re gbo ;


Mo duro de oro Re,
Mo fe gb’ohun iwosan Re,
Je k’emi gbo; Oluwa
Krist’ mo t;eti sile
S’ohun t’O fe wi fun mi,

2 Ma wi,yala l’ohun jeje


Ma je k’emi lo laigbo;
Ma wi,Oluwa,Iwo mo
Gbogbo ero okan mi
Iwo m’ohun ti mo fe
O mi di eni ‘’bukun

4 Mawi,je ki emi mura


Bi mo ba tigb’ohun Re
Pelu;gboran ati ayo
Ni ki nfi tel’oro sile
Kristi,mo teti sile
Ma wi, Oluwa ma wi
Amin
451
6.6 6.6D
Emi o si pelu enu re Emi o si ko o li eyiti iwo o wi Eks 4:12

1 mf Tan’mole Re si wa
L’oni yi,han wa
Fi ara Re han wa;
N’nu oro mimoRe
Jo m’okan wa gbona;
Ka ma wo oju Re
K’awon ‘mode le ko
Iyanu ore Re

2 mp Mi si wa, Oluwa
Ina Emi mimo’
cr Ka le fi okan kan
Gbe oruko Re ga jo eti igbo
Ati ;okan ironu,
Fun awon ti a nko
L’ohun nla t’O ti se

3 mf Ba ni so Oluwa ,
Oro Re ti a nso ‘
Jeki eko oro Re
Gegebi oro Re
K’awon agutan Re
Le ma mo ohun Re
Ibit’O nto won si
cr Ki won si le ma yo
K’ife Re je tiwa ‘
Iwo nikan lao fi
Ipa wa gbogbo sin’
K’iwa je eko
Fun awon omo Re;
di Ko si ma kede Re
Ninu gbogbo okan.
Amin
452
7.7.9.7.7.10.&.Ref
Kiyesii, Igboran san ju ebo lo. I Sam. 15:22

1. mpB’Olorun oba orun


Ti ma nsoro n’igba ni;
O tun ba wa soro be loni
Arakunrin, oto ni
Ohun t’o ba wi fun o:
Ohun kan l’aigbodo mase gboran
mp Sa gboran, sa gboran,
Eyi ni ‘fe Re,
‘Gbat’ oba ranse si o:
Ohun kan ni ki o se
Sa gboran, sa gboran.

2. cr Bi o ba je t’Oluwa
O ni lati gbo tire,
Ko s’ona ‘hinrere miran mo,
Mase sa ase Re ti,
Ma si se lo oro Re,
‘Gba t’olugbala ba nsoro, sagbo.

3. mf Bi o ba fe ni ipin
Ni ‘lu daradara ni
Leyin aye wa buburu yi;
Bi o ko tile m’ona
Krist’ y’o wipe, ‘tele mi
Igbagbo yo si wipe “sa gboran”.
Amin
453
8.8.9.8.&.Ref
Oro Re ni fitila ese mi ati imole si ipa ona mi,OD 11:105.

1 f Bibeli iwe iyanu


Ti o nf’ona han araye’
Fitila ti ntan si ona wa
Lat’ aye yi s’oke orun,
ff Tan ‘wo ‘mole at’ oke wa,
Tan si okunkun aye yi
Tan ninu oru ‘yemeji
Titi oro titun yo fi de,

2 mp Bibeli,ofin Oluwa
Ti o kun ore-ofe’
Ni pipamo re, ere nla mbe,
N’nu re la ri’ye ailopin,

3 mf Bibeli iwe imole


Ti o an lati oke wa;
Iran wo ti o l’ogojulo
Da ‘ma ife si okan wa’
Amin
454
6.4.6.4.D
Jesu wi fun won pe, e wa jeun owuro Jn21:12

1 mp B’onje iye fun mi


Oluwa mi’
B’O ti bu akara
Lebaodo’
Ninu iwe mimo
Ni mo nwa O
Okanmi nfa si O,
Oro iye;

2 mf Wo li onje iye,
Oluwa mi,
Otito oro Re
Ni yo gba mi,
cr Jeki nje ninu Re
Ki mba O gbe;
Jeki nfe oto Re
Ife ni O

3 p Ran Emi Re simi


Oluwa mi’
Ki oO si la’ju mi,
cr Ki nle riran,,
mf Otito oro Re
Fi han fun mi,
cr Ki nri O, oluwa
N’nu iwe Re.
Amin
455
8.8.8..D
Ki iwo ki o si ma fi won ko awon omo re nigbati iwo ba joko ninu ile reDeut.6:7

1 ,mf Nigbati mo joko n’ile mi,


Ki iwe Re se’keji mi’
cr Ki nma f’ayo ka oro Re
Ki nsi ma rohun ife Re
Ki nwadi oro mimo na
Titi yoo fi je temi,

2 mf Je k’oro-ofe Re
Je kiki oro enu mi
Be l’oluwa yo ba rin
Y;otikare ba mi soro
Be l’okan mi yo m’oju Re
Y’o si kun fun ‘fe ailopin .

3 mf Nigbati mo ba dubule,
Jeki oro ilana na
Ki o fi aya mi bale,
Ki nsimi laya Baba mi,
Ki nsun finafon ki nsi l’ayo
Ki nsi r’iran ayeraye,

4 f Ki nyin Oluwa ‘gba mba ji


Ki nkede Re l’ojo gbogbo,
Ki nje k’oro or’ofe Re
Kun okan ati ahon mi,
cr K’ife Re gba emi mi kan.
Si ka mimo ijo t’oke.
Amin
456
8.7.8.7
Ibukun ni fun awon ti ngbo oro Olorun ti nwon si npa mo,Lk.11:28

1 mf ‘Bukun wakati na ti to,


Jesu, t’as sunmo O,
Lati gbo oro yebiye
Ti nti enu Re jade

2 Pelu wa loni bukun wa,


Ka ma j’olugbo lasan’
Te oto Re mo wa l’aya,
Ti mbe n’nu oro iye.

3 f Wo wa b’a ti nwa igbala ,


Ti a joko l’ese Re
A reti ni iparoro
Lati gb’ohun didun Re

4 mf La wa n’iye k’O si to wa
L’alafia l’ona orun
F’atupa oto saju wa,
Ki a ma ba sina lo,

5 Se wa l’eni tutu ,pele


K’a ma f’igboya s’oto
cr L’okun lo, ka ma kose,
Ko s’ewu ninu ‘mole

6 mf F’imole ife agbara


Fun oro Re lat’ oke
Ko ma sise b’iwukara
Ni inu wa titi lo

7 f Ran wa lowo, ka le jeri


Si otito t’a dimu;
Ka si je k’awon elomi
To adun oto na wo,
Amin
457
7.7.7.7.7
Emi ti fe ofin Re to! Ps. 119:97

1. mfBibeli mimo t’orun


Owon isura temi
‘Wo ti nwi bo mo ti ri
‘Wo ti nso bi o ti wa.
2. p ‘Wo nko ni bi mo sina
cr ‘Wo nfi ‘fe Oluwa han
‘Wo l’o si nto ese mi
mf ‘Wo l’o n dare at’ebi

3. f ‘Wo ni nma tu wa ninu


Ninu wahala aye;
cr ‘Wo nko ni nipa ‘gbagbo
Pe, a le segun iku.
4. f ‘Wo l’o nso t’ayo ti mbo
At’iparun elese
Bibeli mimo t’orun
Owon isura t’emi.
Amin
458
6.6.6.6
Oro re ni fitila fun ese mi ati imole si ipa ona mi. Ps. 119. 105

1. mfJesu oro Re ye,


O si nto ‘sise wa,
Eni t’o ba ‘gbagbo
Y’o l’ayo on ‘mole.

2. p Nigb’ota sunmo wa,


Oro Re l’odi wa,
Oro itunu ni,
Iko igbala ni.

3. p B’igbi at’okukun
Tile bo wa mole;
cr ‘Mole Re yo to wa
Y’o si dabobo wa.

4. mf Tani le so ayo
To le ka isura
Ti oro Re nfi fun
Okan onirele.
5. Oro anu o nfi
‘Lera fun alaye;
Oro iye o nfi
p Itunu f’eni nku.

6. mf Awa iba le mo
Eko ti o nkoni,
Ki a ba le fe O
K’a si le sunmo o
. Amin
459
7.6.7.6.D
Oro Re ni fitila fun ese mi ati imole si ipa ona mi,OD119:105

1 f Iwo oro Olorun ,


Ogbon at’ oke wa;
Oto ti ki yipada ,
Imole aye wa;
cr Awa nyin O fun ‘mole
T’inu, iwe mimo;
Fitila ese wa
Ti ntan titi aye

2 mf Oluwa l’O f’ebun yi’


Fun ijo Re l’aye,
A ngbe ‘mole na soke
Lati tan y’aye ka,
Apoti wura n’;ise,
O kun fun otito
Aworan kristi si ni,
Oro iye , toto

2 f O nfe lele b’asia


T’a ta loju ogun’
O tan b’ina alore
Si okunkun aye;
Amona eniyan ni,
p Ni wahala gbogbo
Nin arin omi aye
cr O nto wa soso krist’

4 f Olugbala se ‘jo Re
Ni fitila wura
Lati tan imole Re
Bi aye igbani ;
Ko awon ti o sako ,
Tit’ okun aye y’opin,
Ti won o r’oju Re,
Amin
460
C.M
Oluwa ise Re po ti po to OD.104l:24
1. mf Iwe kan wa ti kika re
Ko soro fun eniyan
Ogbon ti awon to ka nfe
Ni okan ti o mo.

2. mf Ise gbogbo t’Olorun se


L’oke nile n’nu wa;
A ko won sinu iwe na
Lati f’Olorun han.

3. Awosanma t’o ga julo


Dabi ‘fe Olorun
Labe eyi ti gbogb’eda
Mbe li alafia.

4. Okun, lati ayeraye


Nfi egbarun ahon
Kede oko to ga julo
Pe l’awon angeli.

5. mf Iwo ti o je ki nle ri
Ohun to dara yi;
Fun mi l’okan lati wa o.
K’a ri O nibi gbogbo.
Amin
461
C.M
Iltana re li ti o ti nse orin mi ni a ile atipomi OD.119:34

1 f Baba orun nin ;oro Re


L’ogo ailopin ntan
Titi lae la ma yin O;
Fun Bbeli mimo

2 mp Opo’tunuwa ninu re
Fun okan alare
; Gbogbo okan ti ongbe ngbe
Nti omi iye mu,

3 To wa s’otun ka n’ipin
Nibi t’ayo gbe wa;
Mu wa de odo Olorun,
Ka simi n’nu iye mu

4 mf Iba le ma je ayo mi
Lati ma ka titi;
cr Ki nma ri ogbon tiun ko
N’nu re lojojumo.

5 mf Oluwa oluko orun.


Mase jina si mi,
Ko mi lati fe oro Re
Ko mi lati si mi,
Ki nri Jesu nibe.
Amin
462
C.M
Oro mi ki yio pada sodo Mi lofo. Ise 55:11

1 mf Olorun,a so oro Re,


Bi ‘rugbin lor’ile’
Je k’iri orun se sile
Kko mu ipa re wa.

2 K’ota Kristi on eniyan


Ma se sa ‘rugbin na,
K’o f’idi ,mule f’okan wa
K’o dagba ni ife

3 cr Ma je ki aniyan aye
Bi irugbin yi je
K’o si so eso ororun ,
F’alafia at’ ayo,

4 Olorun jo,sokale wa,


F’agbara f’oro ite,
Ki gbogbo okan to gba O
Le mo ibala Re,
Amin
463
6.5.6.5
Ma wi Oluwa, nitori iranse Re ngbo 1st Sam. 3:9

1. mpBa mi soro Jesu,


Mo nduro de O;
Ko mi ba ti nduro
Lati gbohun Re.

2. Ba mi so, Oluwa,
Ni wakati yi,
Je ki nri oju Re,
Alagbara Re.

3. Oro enu Jesu,


Oro iye ni;
Onje atorun wa,
Ma fi b’okan mi.

4. mf Fi kun mi, Oluwa,


Ekun Emi Re,
Bi iri la t’oke,
Jek’o ba le mi.

5. mpMo f’ara mi fun O,


Ki nle je Tire,
Emi, okan, ara,
Fi mi se tire.
6. cr Ma wi Oluwa, wi,
Iranse Re ngbo,
Emi nteti lele,
Lati gbo’ro Re.

7 . Fun mi ni imo si,


Ki nmo ife Re,
Ki gbogbo ife Re
Lese ninu mi.

8. Bi igi ti a gbin,
Si eba odo;
Be ni ki aye mi,
Ma mu eso wa.
Amin
464
8.8.8.8D
Gbogbo iwe mimo ti o ni imisi Olorun li o si ni ere fun eko .II Tim,3:16

1 mp Nipa imisi Re l’awon


Mimo igbani k;oro Re,
B’o ti wa lateekose
Be lo wa titi d’isiyi;
Iye ti mbe n’nu oro na
Ijo,mi si inu okan wa,

2 B;a ti nka oro mimo na,


Pelu adura at’ife
Ran Emi Re lat’oke wa
Ki o le so okan wa ji,
Le gbogbo okunkun wa lo,
F’imole Or’ofe to wa.

3 p Nigbati a ba si sako,
Ti a ko Olorun sile
Jo,fi oye ese ye wa,
Ba wa wi,si mu wa pada,
Mu wa banuje f’ese wa,
Si f’oro Re tu wa ainu.

4 cr Mu wak’eko ore-ofe
Lati inu oro iye,
Ko wa ni gbogbo ona Re.
Mu wa mo pipe ife RE,
Mu gbogbo ipinnu Re se,
Sowa di okunkun pipe

5 cr Pese wa fun ise rere’


Ohun eto ta ya soto
K’a je iranwo f’omi
Ni ipokipo ti nwon wa,
Lati oro won, lati ko won,
L’ona iye ainipekun.
Amin
465
L.M
Oro re dun ju oyin lo li enu mi, OD 119:103

1 mf1Didun l’oro Re je fun mi,


Oluwa ,mo ti fe won to,
Imole re ntan lat’ oke wa,

2 f Mo ri ayo nin Oro na,


Isura iyebiye ni,
Lati mo ijinle ‘fe RE
Lati ma w’ogo ite Re

3 cr Ogbon eniyan ko le ko,


Oye eniyan ko le mo,
Nipa imisi Re nikan
L’a fi ko iwe mimo na,

4 mp Iwe iyanu n’Iwo gbe


Le awa eda Re lowo ;
Awon eni-mimo ‘gbani
Nipa Emi,won kowe na,

5 f Omi iye ni f’okan wa


Eko re nmu inu wa dun
O nso ‘gbagbo at’ ife ji,
O nmu ki ipe wa daju

6 mf Iwo otito at’ ife


Ti o nf’ona iye han wa,
F’ore-ofe fun gbogbo wa
K’a je pipe niwaju Re .
Amin
466
7.6.7.6 D.&Ref
Ki o si gbo gbogbo eyiti Oluwa Olorun wa yio wi Deut 5:27

1 p Ba mi soro Oluwa
Soro l’ohun jeje
Ki ngbo ohun ife Re,
Emi wa pelu re.
Lu mi ni ookan aya
Ki nyara gbohun Re’
F’’orin kuro okan mi
Ki ni l’ayo ninu Re
pp Wi fun mi l’ohun jeje
Ohun ife didun,
Pe un o ju asegun lo,
Un o bo patapata’
‘Jojumo ki nle ma gbo’
Ohun Emi didun
Soro na fun mi loni;
‘Emi wa pelu re’

2 mpWa b’awon ‘mo Re soro


To won s’ona mimo
Fi ayo kun okan won
Fi adura ko won’
Ki won f’ara won rubo,
K’ijoba Re yara de
K’oju wa le ri O,

3 mf Soro bi ti igbani ,
Fi ife Re han w
Ki nmu gbogbo ise mi,
Ki nmu ase Re se
To mi ki ngb’ogo Re ga,
Ki nfi iyin Re jise Re
Ki ngbe O ga titi.
Amin
467
C.M
La mi li oju emi ki o le ma wo ohun iyanu wonni lati inu ofin re OD,119:18

1 mf Baba eda,n’nu Eni ti


A wa ,a nrin,anmi ;
Ran’tansan orun sokale,
Wa mu wa laraya.

2 p ‘Gbati a nwa On’nu oro Re


Pelu iwariri
Le wa l’oju sije k’a ri
Iyanu ofin Re

3 mpJeki okunkun wa le ri
‘Mole ti ntan sansan ‘
Ran Emi ‘fihan sokale
Fun wa l’eti ‘gboran,

4 cr Mu ore Re ti a gbagbo
Koja niwaju wa
Jek’a r’oju Re n’nu Jesu
K’a ko ohun aye
Amin
468
8.8.8.D
Oro re ni fitila fun ese mi, ati imole si ipa mi,OD,119”105

1 mf WA iwo woli Oluwa ,


Ogbufo nla ti Olorun,
Se’tumo oro Re fun wa,
Iwo nikan l’o le ko wa,
Jowo, mas’aif’ara Re han,
Si iwe Re lasipaya ,

2 mpKristi,f’oro woli han wa,


Ti won ti so ni ipa Re
Olu oro iwe mimo,
Nipa Re l’a ko gbogbo won
Sibe ao le ri O nigbe,
Bi Emi Re ko si fun wa,

3 mf Jesu,mu ‘boku wa kuro


Ati airiran okan wa,
Fi iyanu ife Re han,
Jeki a mo O b’o ti ye
Te ti on okan wa ba
Ma wi,n’tori ‘ranse Re ngbo.
Amin
469
C.M
Ifihan oro Re fun ni ni imole’ o si fi oye fun awon ope OD 119:130

1 mpEmi nmi s’ori oro na,


O nf’ oto re han wa;’
Ilana oun ileri Re
Ntan imole mimo.

2 f Ogo kan yi iwe na ka,


O mole bi orun ;
Imole ti ko ainpekun
L’o nikan fi fun ni,

3 mf Emi t’o oro I fun wa’


O mbe sibesibe
Oto Re yo s’oril’ede
O yo,ki o wo mo,

4 ff Jek’a f’ope aiti fun O


Fun iru mole yi,
T’O mu ki imole orun
Tan s’okunkun aye

5 f Okan mi nyo lati lo ‘pa


Es’eni mo fe,
Titi un o fi ri ogo RE
L’aye didan loke
Amin
470
11.10.11.10..&Ref
E ma wa inu iwe mimo John 5:39

1. f Di Bibeli mu b’ohun miran kuna


Ma so ilara Re to s’owon nu
Ihin ayo Re nji okan ti ntogbe,
Iye si ni ‘leri re je fun o,
ff Di Bibeli mu! Di Bibeli mu!
Oluto, amona lo je fun wa.

2. mf Di Bibeli mu ‘sura ‘yebiye ni


O nf’iye ainipekun f’araye,
Ko si eda na to le won iye re
Wa ibukun re nigba to le ri.

3. f ‘Mole ni fun gbogbo awon asako


Amona fun odo t’iba subu
‘Reti f’elese t’aye re ti daru
Opa f’ogbo iwe to dara ju.
Amin
471
8.8.8D.
Iwe mimo ti o le mu o di ologbon si igbala,II Tim 3:15

1 mf Mo feran iwe oroRe


Of’imole at’ ayo fun
Okan okun on ‘banuje
Oro Re t’ona mi wiwo’
Eru Re ko jeki nsirin,
‘Leri Re m’okan mi simi

2 mf Eru Re ji mi n’nogbe mi
O so blt’ewu mi gbe wa’
Sugbon Oluwa oro Re
di L’o so okan mi di mimo,
L’o te ori ese mi ba
L’o si m’ere nla wa l’ofe

3 mpTani mo ebi okan re?


Dari sise koko ji mi,
di Gba mi low’ese agidi,
K’O si gba iyin rele mi,
Fun aika we ore-ofe
At’ eri iser Re lasan.
Amin
472
C.M
Omokunrin tujuka a dari ese ji o, Mat 9:2

1 f Jesu mi,mu mi gb’ohun Re


S’oro alafia ‘
Gbogbo ipa mi y’o dalu
Lati yin ore Re

2 p Fi iyonu pe mi l’omo,
K’O si dariji mi,
Ohun na yio dunmo mi,
B’iro orun,

3 f Ibikibi t’O to mi mi,


L’emi o f’ayo lo
Tayotayo l’emi o si
Dapo m’awon oku

4 f Gba eru ba koja


Eru mi ko si mo ;
Owo t’o fun dariji ka.
Y’O pin ade iye.
Amin
473
C.M
Nipa ewa li odomokunrin yio fi mu ona re mo ?
Nipa ikiyesi gege bi oro re OD 119:9

1 mf Bawo ni awon ewe wa,


Y’o ti ma soro won
Bikose nipa kiyesi,
Gege bi oro Re

2 Gba oro na wo ‘nu okan


A tan imole ka
Oro na ko ope l’ogbon,
At’ imo Olorun ,

3 f Orun ni,imole wa ni,


Amona wa l’osan’
Fitila ti nfonahan wa,
Ninu ewu oru

4 Oro Re oto ni titi,


Mimo ni gbogbo re
Amona wa l’ojo ewe,
Opa l’ojo ogbo,
Amin
474
C.M
Mo ri oro Re mo si je won jer

1 mf Bibel’ iwe ayeraye


Tani le r’idi re?
Tani le so idide re

2 f Asiri Olodunmare
Iko Oba orun’
ff Ida t’o pa oro iku’
Aworan Olorun

3 mf Okan ni O larin ogo


Iwe aye ‘gbaini,
Iwo l’o s’ona igbala
Di mimo f’araye

4 mf Isura ti Metalokan ,
ff Oba nla t’oO gun wa’
Je tumo aras re fun mi,
Ki m’ye siyemeji,

5 Ki’m’si o pelu adura


Ki ‘m’koko ninu re
Iwo iwo ayeraye
F’ife Jesu han mi,
Amin
475
8.8.9.8.8.8.8.4
La mi li oju li emi ki o le ma wo ohun iyanu wonni lati inu ofin Re,OD.119:18

1 mpLa mi l’oju ki mba le ri


Oro otito Re fun mi’
Fi ijinle ife Re han mi,
Ti y’o so mi di ominra
p Ni ‘dakeje ni mo nduro
Mo mura lati se ‘fe Re
La mi l’oju,mu ‘mole wa
Emi Orun.

2 mf Si mi l’eti ki mba le gbo


Ohun otito Re fun mi;
Je ki iro opo ohun Re
Tu gbogbo etan esu ka;
p Ni ‘dakeje ni mo nduro,
Mo mura lati se ‘fe Re
Si mi l’eti mu mole wa
Emi Oorun

3 mf La mi l’ohun ki mba le so
Oro otito Re yika
Ro mi l’okan ,mura mi sile
Ki nle to adun ‘fe Re wo
p ni ‘dakeje ni mo nduro,
Mo mura lati se fe Re
Ro mi l’okan .mu mole wa
Emi Orun

4 mpSi mi n’iye,ki mba le ka


Ti ife Re nin orro Re
kini y’o tun ma deruba mi,
Gbati mole Reba nto Re
p Ni’dakeje ni mo se’fe Re
Mo mura lati se’fe Re
Si mi ni ye.mu mole wa.
Emi Orun.

5 La na sile k’emi le mu
Ebun ofe wa f’Oba mi’
N’’nu ife ‘oro Re y’o dun ju
Orin t’awon angeli nko
p Ni ‘dakeje ni mo nduro
Mo mura lati r’ife RE
La na sile mu mole wa,
Emi Orun.
Amin
476
C.M
Okan wa ko ha gbina ninu wa nigbati O mba wa soro li ona LK,24:32

1 mpBa wa soro f’ara han wa,


Lona ajo aye
B’okan wa soro ;jek’a mo
Igbona ife Re

2 O mba wasoro ,a gbagbe


‘Gba lala at’ apon’
Lala je simi rora a dun
B’Olorun wa nihin

3 mf Olorun mi,jo ma gbe ‘hin


jek’okan mi ma yo’
Okan mi y’o gba ase Re’
Y’o si je ipe Re

4 cr ‘Wo pemi ki nwa oju Re


On ‘na ni mo fe wa’
Mo fe teti s’or’ofe Re
Ki nsi gbo ohun Re

5 f Jeki af’eyi ise mi mi


Titi un o r’ogo Re,
Ti un o bos’ayo Baba mi,
Ninu alafia
Amin
477
7.7.7.7D
Eyi ni ayanfe omo mi eniti inu dun si gidigidi Mat.3:17

1 mpJesu ti o gba mi la
Wo nu odo Jordani’
O jade kuro n’nu re
A si m’O l’om’Olorun,
Nipa ohun ‘fe Baba ,
At’ iwa le adaba ‘
Jesu Olutot’emi
Bi Rre mo fe tegbomi

2 pp Nin’ogba ba ibanuje
Bo okan Re bi omi’
Ni kalfari l’origi
A ni Jesu ku fun mi,
Akan mi po pelu Re
Reti mi ni pe o ku
Mo ni po mi lese Re
Mo njiya nitori Re

3 p N’nu boji titun lo sun’


O mu eru Rre kuro’
O la ‘kuta re koja
O l’ ogo titi laelae ‘
Mo fe ka sin mi mo krist’
Nin ase ta bere yi’
Bi mo si ti ayo s’oke,
Ki nwa l’etun s’Olorun
Amin
478
10.10.10.10.10.&Ref
Kiyesi iru ife ti Babafi fun wa, pe ki a le ma pe wa ni omo Olorun Ijn.3:1

1 f Moyo pupo pe Baba wa Orun


So t’ife Re ninu ‘we t’O fun mi
Mo r’ohun ‘yanu ninu Bibeli ,
Eyi s’ owon ju pe,Jesu fe mi,
ff Mo yo pupo pe,Jesu fe mi,
Jesu fe mi Jesu fe mi,
Moyo pupo pe Jesu fe mi,
Jesu fe an’ emi,

2 mpGba mo gbagbe Re ti emi le ko,


O fe mi sibe ,O wa mi kiri,
Mo yara pada s’apa anu Re,
‘Gbati mo ranti pe jesu fe mi,

3 f Bi o se orin kan l’emi le ko,


‘Gba mo r’Oba nla ninu ewa Re,
Eyi ni yo mu j’orin mi titi,
A yanu si pe ,Jjesu fe mi

4 p Jesu fe mi,mo si mo pe mo f’E


Ife lo mu wa r’okan mi pada
Ife lo m’U k’o ku l’ori igi
O da mi loju pe,Jesu fe mi,

5 mpEmi o ti se dahun b’a bi mi


Ohun ti ogo Oluwa mi je’
Emi mimo njeri nin okan mi,
Ni igba gbogbo pe,Jesu fe mi,

6 f Ni ‘gbekele yi ni mo r’isimi ,
N’igbekele krist’mo d’alabukun,
Satan damu sa kuro l’okan mi,
Nigba mo so fun pe,Jesu fe mi,
Amin
479
C.M
Gbogbo wa ti a ti bapitisi sinu Kkristi Jesu a ti baptisi wa sinu iku Re Rom. 6:3

1 mf Jesu,Iwo l’a gb’ohun si,


Mi Emi Mimo Re
Si awon eniyan wonyi,
Baptis’ won s’iku Re

2 mp K’O fi agbara Re fun won,


Fun won l’okan titun’
Ko ‘ruko Re si aya won,
Fi emi Re kun won

3 mf Jeki won ja bi ajagun


L’abe opagun Re’
Mu won f’otito d’amure,
Ki won rin l’ona Re

4 mp Oluwa,gbin wa s’iku Re
K’a joguniye Re,
L’aye ka ru gbelebu,
K’a ni ade oeun,
Amin
480
8.7.8.7
Baptisi won li oruko Baba ati ni ti omo ati ni ti Emi mimo ,Mat 28:19

1 mf Wa Emi Mimo sokale


Oni baptisi okan wa’
M’edidi maemu Re wa,
K’O si se eri omi yi,

2 ff Tu agbara nla Re jade,


K’O si won eje etueu’
Ki Baba ,Omo at’ Emi,
S’awon yi omo Olorun,
Amin
481
S.M
Dide,Ki a si baptisi re Ise A 22:15

1 f Duro,Om’ogun krist’,
F’enu re so f’aye,
Si jeje pe, ‘ofo l’aye’
Nitori Jesu re,

2 mf Dide,ka baptis’ re,


Ko we ese re hu
Wa b’Olorun da majemu
Jewo igbagbo re,

3 cr ‘Wo ki se t’anu re
Bikose ti krist;
A ko oruko re po mo,
Tawon mimo gbani

4 mf Nni hamora Jesu


Kojuja si esu’
Bo ti wu k’ogun ni,
Awa ni yo segun,

5 f Ade didara ni,


Orin na,didun ni,
‘Gba ta ba ko okigun jo,
S’ese Olugbala ,
Amin
482
8.7.8.7.
Nitorina lo,e ma ko orile-ede bogbo,ki e si ma baptisi won li oruko Baba,ati ni ti omo ati
ni ti Emi Mimo Mmat,28:19

1 mf Eni rele t’nwa’gbala


Nip’eje Od’-agutan,
E gbo ohun Isipaya,
E rin na ti Jesu rin,

2 mf Gbo Olugbala t’Onpe yin


F’eti s’ohun Re orun,
di Ma beru e yan ona Re

3 mf Jesu wipe,Se tebomi


Fun awon t’o gbaMi gbo,
A te on papa bo mi ri,
Ninu odo Jordani,

4 mf E to ipase Re nihin,
To lehin nduro pe,
E fi ayo gba ase Re
Wo Olori yin saju,
Amin
483
C.M
Eniti on tikarare fi ara re ru ese wa da ori igi I pet.2:24

1 mpOluwa,nje dariji Re
Yio gb’eni bi emi’
Nje,O gba ese mi kuro
O f’erin bukun mi,

2 Nje fun mi l’O r’agbelebu


Li nani egan Re
Jesu ,o ha to ki ntiju
Biba O lo s’odo

3 O se ‘ra Rre l’apere nla,


Li odo Jordani/
Igbaerga mi yio mi ba ko,
Lati s’ohun t’O se,

4 Jesu,itara ife RE
p Mba ilora mi wi,
Ese mi nisiyi si rin
Lo ona didun Re,
Amin
484
C.M
Bi a ti sin nyin po pelu re nipa baptismu nipase eyiti a si ti ji nyin
dide pelu re nipa igbagbo ti ise iseOlorun Ko 2:12

1 mf A Baptis’ wa sinu iku


Nipa itebo mi
A sin wa ‘mu boji Jesu,
A sin wa pelu Re

2 A ba kris’ ku k’a ye se
K’a le ji pelu Re
K’a le jere ebun titun
T’y’o mu wu ye f’oke

3 p Emi fi ara Re fun wa,


K’oro wa ko le je
Ierti Oluwa l ‘oke
At’ ifarahan krist’

4 Fun igbagbo wa li ogo’


Ayo ati ade
Lat’ aye k’a le wa l’oke
K’a joko pelu krist’
Amin
485
L.M
Nje a si baptismnu sin wa po pelu re sinu iku Rom 6:4

1 mpA ko gb’oro wuwo ni,


T’asin wa pelu Oluwa
P’a te wari sinu ‘ku Re
A si bo ara osi Re,

2 f Okan wa gba emi t’orun,


A gbe kuro ninu iku
Beni kris’ jinde n’iboji,
O si mb’Olorun gbe l’oke

3 mpK’a ma jek’esu tun joba


Ninu ara iku wa mo,
Gbogbo ese ti a ti nda
Ki yio j’oba l’ori wa mo,
Amin
486
L.M
Enikeni ti o ba gba a gbo ki yio segbe,sugbon yio ni iye ti ko nipekun Jn,3:16

1 mf Oluwa orun at’aye


Jesu,Omoninu ara
Emi mimo fun toju wa
E gbo,ki E si gb’eje wa,

2 mpA gba O,Jesu ti a pe


A gba wo t’O r’oke orun
Pelu Rea ti ku s’ese’
Okan wsi nfe ba O ji,

3 A gba ihinrere Re gbo,


A nlo,owo Re yio to wa,
L’odo Jordani s’nw’ ona
T’awon Tire gba d’odo Re

4 p Nipa’tebomi ami nla


Awa fi ara wa fun O,
F’edidi te majemu na.
K’O gba la fun Tire
Amin
487
L.M
Eyiyi li ayanfe Omo mi,eniti lnu mi dun si gidigidi,e ma gbo ire Mat 17:5

1 mf Gbo ohun t;o dun lat’oke


Si Jesu l’odo Jordani,
Eri fun gbogbo araye
‘Eyi l’ayanfe Omo Mi,

2 Alailese,Eni pipe,
Sugbon nitorit’a pase
Iwenumo ninu odo,
O f’ara Re se apere ,

3 Omo okan aya Baba


Igbala fun gbogbo eda
Orisun iye elese,
Jordani t’oke Kalfari,

4 Wa tele Olugbala re,


Ninu ase ilo s’odo,
Apere iba Jesu ku
Ati ajinde pelu Re

5 f Wa ma tan idi asiri


T’owu Oluwa lati bo,
F’igboran saju nikehin
Ere te y’o fi ara han
Amin
488
8.7.8.7.4.7
Eni ti o ba gbagboti a ba si baptisi re yio la sugbon eniti ko ba gbagbo yio jebi,Mk.16:16

1 mf Wo awon t’o wo so ala


Won duro loni odo
Won k’eyin s’ayeat’ esu
Won ntele

2 mf Wo bi won ti duro leru


Sugbon pelu ireti
Won mo pe Olugbala won
L’o pase odo lilo,
f Jordan’tutu,
Sugbon igbagbo gbona,

3 mf Si awon arakunrin
Egbon won ninu Jesu
Wo bi won ti na wo ife
Won sa ti dabi won ri
Nisisiyi,
Won ny’ayo idariji

4 f Lo,tele Olugbala yin,


E f’oju igbagbo ri,
A orun si,Emi Baba
Si nke lat’ oke wipe
ff ‘Awon wonyi
Ni ayanfe Oomo Mi,
Amin
489
7.6.7.6.D
Onwasi baptisimu ironupiwapada fun inukuro ese Lk.3:3

1. mf Ohun ti ndun l’aginju,


Ohun alore ni,
Gbo b’o ti ndun rara pe,
“E ronupiwada”
Ohun na ko ha dun to?
Ipe na ko kan o?
Ki l’o se. arakunrin,
Ti o ko fi mi ra?

2. f “Ijoba ku si dede”
Ijoba Olorun
Awon t’o ti fo ‘so won
Nikan ni yio gunwa
Ese t’o ko fi na ni
Ohun alore yi,
Ti ndun l’eti re tantan
Pe, “Ronupiwada?”

3. mfAbana pelu Fapati


Le je odo mimo
sugbon ase ‘wenumo
Jordan ‘nikan l’o ni
Ju ero re s’apakan
Se ase Oluwa,
Wa sinu adagun yi,
We, k’o si di mimo.

4. mf Kin’ iba da o duro?


Awawi kan ko si;
W’odo, wo Johannu re,
Ohun gbogbo se tan;
O pe ti o ti njiyan,
O ha ba Emi ku?,
Elese gbo alore
Si ronupiwada.
Amin
490
9.7.10.7.&.Ref
Eje Jesu kristi Omo Rre ni new wa nu kuro ninu ese wa gbogbo I Jn.1:7

1 f Agbara mbe n’nu eje Jesu


‘Tori w’ese mi nu,
Mo si mo pe isin Re li ayo,
O’s’okun mi idi mole
ff Agbara mbe,agbara t’o sise ‘yanu
Agbara mbe,agbara ti o new wa mo,
Mbe ninu eje Jesu

2 mf Emi mo ire t’eje na nse,


O gba mi lowo ebi,
‘Gbati mo k’eru ese mi to wa
Eje Re ti we mi mo,

3 f Emi mo ire t’eje na nse


O ti so wa di titun
Nipa eje Re iyebiye na,
Mo mimo titi lae
Amin
491
L.M

Emi li onje iye na,Jn.6:43


1 f Jesu,ayo okan gbogbo,
Orisun’ye imole wa,
di Nin’opo bukun aye yi
cr Laintelorun,at’ O wa

2 f Otito Re duro laelae


p Won gb’awon to kepe O la,
cr Awon ti o wa ri O,
f Bi gbogbo nin ohun gbogbo

3 mf A to O wo Onje Iye
A fe je l’aras Re titi,
Amu ninu Re ,Orisun,
Lati pa ongbe okan wa,

4 p Ongbe Re sa ngbe okan wa


Nibikibi o wu k’a wa
cr ‘Gbat’ aba ri O awa yo,
f Ayo nigbat’a gba O gbo,

5 mp Jesu wa ba wa gbe titi,


Se akoko wa ni rere
cr Le okunkun ese kuro,
ff Tan ‘mole Re mimo s’aye
Amin
492
C.M
E ma se eyi ni iranti mi Lk,22:19

1 mf Gege bi oro ore Re,


Ninu irele nla,
Emi o se yi Oluwa,
p Emi o ranti Re

2 mf Ara Re ti a bu fun mi
Yio je ounje mi,
Un o gba eje Re
p Lati se rnti Re

3 mpMo le gbafgbo Gethsemane,


Ti mo r’ijamu Re
pp Iya on ogun eje Re
cr Ki nma si ranti Re

4 Gba mo ba now agbelebu ,


Ni oke Kalfari;
Wo Od-agutan Olorun
Dandan,un o ranti Re

5 mpUn o ranti gbogbo ‘rora Re


At’ ife Re si mi,
cr Bi o ku emi kan fu mi
Emi o ranti Re

6 pp Gbati enu mi ba pamo,


Ti iye mi ba ra,
cr Ti o ba de n’ijoba Re
Jesu,jo ranti mi,
Amin
493
6.6.6.6
Ounje na ti emi o si fifun ni li ara mi, fun iye araye John 6:51

1. p Mo nkebi on ongbe,
cr Jesu, se onje mi,
f Tu jade om’iye,
Lat’inu apata.

2. p ‘Wo akara t’abu


Te okan mi lorun,
cr B’ati b’okan iye,
mf Bo mi, ma je ki nku.

3. mp‘Wo ajara iye,


Je ki mno adun Re;
cr Jo, tun okan mi se,
mf Fi ife s’aya mi.

4. p Ona aikuna po,


Ti mo ti rin koja
cr Bo mi ounje orun
di Gba mi, Om’Olorun

5. mfAginju wa sibe,
Ti y’o m’ongbe gbe mi:
f Eyin omi iye,
E ma sun ninu mi.
Amin
494
7.8.7.8.7.&.1
Eje Jesu Kristi ni nwe wa nu kuro ninu ese wa gbogbo st. John 1:17.

1. f Ki l’o le w’ese mi nu,


Ko si lehin eje Jesu
Ki l’o tun le wo ni san,
Ko si lehin eje Jesu,
mp A! eje ‘yebiye
To mu mi fun bi sno
Ko si isun miran mo,
Ko si lehin eje Jesu.

2. f Fun ‘wenumo mi, nko ri,


‘Kan mi, lehin eje Jesu:
Ohun ti mo gbekele
Fun ‘dariji, l’eje Jesu.

3. p Etutu f’ese ko si,


Ko si lehin eje Jesu,
Ise rere kan ko si,
Ko si lehin eje Jesu.

4. mpGbogbo igbekele mi,


Ireti mi l’eje Jesu;
Gbogbo ododo mi ni,
Eje,kiki eje Jesu
Amin
495
10.10
Fi etisi ni ,Oluso-agutan Israeli, iwo ti o nda Josefu bi owo-agutan OD.80:1

1 mf ‘Wo Oba aanu,lat’ ori’te Re


Fi ife wo wa, si gbo ibe wa,

2 mp ‘Wo Olusoagutan eniyan Re


Pa awon agboagutan Re mo,

3 p Olugbala ,iku Re n’iye wa,


F’iye anipekun fun gbogbo wa,

4 cr Onje orun ,iwo ni onje wa,


Se F’’ranwoagbo agutan Remo

5 p ‘Wo l’Alabaro,ore elese ,


cr ‘Wo n’ibu ayo wa titi laelae

6 f Wa l’ore-ofe Re mu ‘nu wa dun


Si je k’a ma ri ojurere Re

7 mf Nigba osan ,ati nigba oru ,


Sunmo wa k’o s’ma d’imole,

8 cr Ma ba lo k’O si ma ba wa gbe
N’iye ,n’iku ma je itunu wa

9 mf L’ojojumo f’oju fe Re to wa
Si mu wa dele l’alafia,
Amin
496
7.7.7.7.D
Oluwa odo tali awa o lo Jn.6:68

1 mf Tal’awa iba to lo,


Bikos’ odo Re Jesu
‘Wo ti se imole wa
At’ iye ainipekun
mp Emi Re ti l’owo to
T’Emi Mimo nmi si wa?
Onje Re Atorunwa
Li okan atunbi nfe

2 mf Israeli li atijo,
Won je manna,won si ku
mp Tal’awa iba ba to lo
‘Gbat’ ibi ba yi wa ka,
cr Bikos’ odo Re Jesu,
‘Wo tise iranwo wa,

3 mf Tal’o le we okan wa
T’o si le gbo igbe wa’
Tani le kunokan wa
Olugbala lehin Re
f Iyin at’ope fun O,
Titi, Wo Olorun mi,
Ninu Re le mi o ma wa,
Ma wa ninu mi titi.
Amin
497
10.10.10.10
Emi o si feran pe ,emi o si fi ara mi han fun Jn.14:21

1 mf Oluwa ,mo mba O pade nihin


Igbagbo mu mi wo ohun orun
Un o fi agbara ro mo ore Re
p Un o fi ara are mi ti O,

2 mf Emi O je akara Olorun ,


Emi o mu waini orun pelu Re
Nihin un o so eru aye kale’
Nihin ,un o gba idariji ese.

3 Emi ko ni’ranwo mi lehin Re


Apa re l’o to lati f’arati,
cr O to wayi, Oluwa mi,o to,
Agbara mi mbe ninu ipa Re

4 cr Temi ni ese,Tire l’ododo,


cr Temil’ebi ,Tire l’eje wenu
mf Ewu abo, on alafia mi,
L’eje at’ ododo Re Oluwa,

5 Gbat’a ba dide t’a si palemo


T’a ko akara ati wain kuro
Sibe iwo wa nihin Oluwa
Lati je orun ai asa mi,

6 di Bi ase yi nde ti o si nlo,


cr O nraan wa leti ase nla t’orun’
f Onfi ayo didun ase na han
Ase ayo,yawo Od,Agutan ,
Amin
498
10.10
Ara mi ti a fi fun nyin ni eyi e ma se eyi ni iranti mi, Lk,22:19

1 mp Sunmo’hin,k’o gba Ara Oluwa


K’o mu eje mimo t’a ta fun O,

2 mp Ara at’ eje na l’o gba o la


cr N’itura okan ,f’ope f’Olorun,

3 f Elebun igbala,omo Baba,


Agbelebu Re fun wa n’isegun ,

4 di A fi rubo fun tagba tewe,


On tikare ran l’ebo,on l’alufa,

5 mf On l’Oludande,om ni imole ,
On nf’Emi ran awon tire lowo,

6 mp Nje e fokan igbagbosunmo,hin,


Ki e si gba eri igbala yi

7 mf On l’onsakoko eeyan Re laye


On l’onf’iye ainipekun fun wa

8 f On nf’onje orun f’awon t’ebi npa,


Omi iye fun okan ti npoongbe,

9 p Onidajo wa, Olugbala wa,


Pelu wa ni ase ife Re yi,
Amin
499
7.7.7.D
Eniyan fi iku Oluwa han titi yio fi de I kor,11:26

1 cr K’on t’o de – je k’oro yi


Ma dun titi l’eti re
Je ki sa a die t’o ku
Itan gbangba daju fun O,
f Ronu b’orun on ile
di Ti d’ehin gbat’ O ba de,

2 p Gbat’ awon ti a feran


Bo si sinmi won loke
T’o pe aye wa pin,
Ti adun re si koro
di E dakun , e ma b’ohun,
cr Kiki k’on to de sa mi,

3 mp Ibanuje yi wa ka,
A ha fe k’o dinkubi?
Gbogbo eru iponju
Gbogbo ofo aye yi,
Iku ofo on boji
p Nso jeje pe,K’on t’o de

4 mf Wo tabli ife a te
Mu waini, si j’akara
‘Ranti didun k’Oluwa
T’o pe wa s’on je orun
p Ni lat’ aye mi l’orun ,
cr Won pinya ti’ on fi de,
Amin
500
C.M
Nwon si nrohin nkan ti o se li ona ati bi o ti di]
mimo fun won ni bibu akara Lk.24:25

1 mf Farahan wa n’ibi onje,


Ma si se lo nihin;
Olugbala ba wa joko,
Ko si ba wa jeun.

2 f Fi ife mimo ba wa jeun’


K’ara on eje Re,
Onje iye,waini t’orun
Ma bo wa titi lae.
Amin
501
7.7.7
Jesu wi won pe, E wa jeun owuro. Jn. 21:12.

1. mf Jesu, lwo t' o pe wa


Si tabili Onje Re:
Fi onje iye bo wa.

2. mp B' ati f'irele kunle


Je k' a mo p'o sun mo wa:
Si f' ife nla Re haan wa.

3. mp B' a ti nwo agbelebu,


p T'a ti nkanu ese wa,
So 'banuje wa d' yoo.

4. mp Nigbaat' a ba mu walni
Ti ns' apere eje Re,
cr F' ife Re kun okan wa.

5. f Fa wa si bi iha Re,
Nibiti isun ti nsan,
Si we gbogbo ese wa.

6. p Jo tu ide ese wa,


Si busi lgbagbo wa,
F' alafia Re fun wa,

7. cr Ma fi owo Re lo wa,
mf Tit' ao fi yi te Re kaa.
f N'ile t' o dara julo.
Amin.
502
11.9.11.9.& Ref.
O fi eje Re we wa nu kuro ninu ese wa gbogboo. Ifi 1:5.

1 mf O ti to Jesu lo fun 'wenumo bi'


A we o n'n' eje Od'agutan'
Iwo ha gbekele ore-ofe Re;
A we o n' n' eje Od'agutan'
A we o n'nu eje
Ninu eje ti nwe okan mo'
Aso re funfun, o si mo laulau;
A we nn' Od'agutan'

2. mf Omba Olugbala rin l'ojojumo


A we n'n' eje Od'agutaan'
O ha gbekele Eni t' a kan mo gi'
A we o n' n' eje Od'agutan'

3. mf Aso re ha mo lati pade Jesu'


A fo mo n'n' eje Od'autan'
Okan re ha mura fun le didan ni'
K'a we n'n' eje Od'agutan'

4. mp Bo ewu eri-ese si apakan'


K'a we n'n' eje Od'agutan'
Isun kan san fun gbogbo okan aimo'
Jo lo we n' n' eje Od'agutan.
Amin.
503
L.M. & Ref
E duro ninu ife mi. Jn, 115:9.

1. mp K rist mimo, Oluwa mi,


Ife Re ju t' aryee lo;
Ore otito li O je
Mo mo pe Oluwa mi ni,
f Oun je t' emi Ore mi owon.
O mba mi gbe nigbagbo:
Ogo didan wa yi l ka,
Ju gbogbo re, Oun je t' emi.

2. mp T'emi ni O sa fun mi
O gba mi gbe nigbagbo;
f Pelu ayo ni mo nke pe,
Ogo ni fun Olrunmi.

3. mf T' emi ni, O ngbe okaan mi


Aki y' o pinya tit’ aye,
Bi eka l' ara ajara
Beni mo je l' ara kristi.

4. cr Lojo kan ni 'lu didan ni


Oju mi y'o ri ogo Re;
Nigbana un o ro mo l’orun,
f Un o fo f'ayo p' On je t'emi
Amin.
504
11.C.437.H.C 141.3.7s
Lati mo ife Kristi to poju imo gbogbo lo Efe 3:19

1. mp Jesu, wo oninuere
Sin wa lo tabili Re
Si f' onje orun bo wa.

2. cr B'a ti kunle yi O kan;


Je ka mo p'o sunmo wa;
Si f' ife nla Re haan ni,

3. Gb'a aba n f' igbagbo wo O


Je, ka mo nsokun ese
So aro wa di aayo,

4. Gbat ta ba f' enu kanwain'


Ti nseapere eje Re.
M' okan wa ife.

5. Fa wa ssibi iha Re
Nibiti itun mi nsan
Si we gboogbo ese nu

6. Jo tu ide ese wa
Si busi igbagboo wa
F' alaafia Re fun wa

7. mf Ma f' owo Re to wa nsso,


Tit’ ao fi de ‘bugbe Re
N’ile to dara Julo,
Amin
505
C.M
Emi ki yio mu ninu ese ajara yi mo titiyioo fi di na, nigbaati emi o si ba nyin mu ti
itun mi ijoba Baba mi Matt26:29

1. mf O jo ko' ase na leyi;


Mo f; ara mi yin;
p E wo mo f; mi fun yin,
Lati ra yin pade,

2. O di ' nu joa Baba mi,


Ki nto tun ba yin mu;
Gbana ekun ko ni ssi mo
A o mi yo titi.

3. mf Titi l' ao ma je yi,


K' o di igba na;
Ka gbogb' aye l'oploplo
Yo ma je, Y' o ma mu.

4. 'Bukun atorun wa y' o mi


Wa lor' awon t' o nje;
Un ogbe or ite Baba mi
Ma pes' aye fun won.

5. p Sugbon nisisyi, ago


cr Kikoro l' em 'o o mu.
Emi o mu nitri yin,
pp Ago rora ikau.

6. p E ko le mo banuje mi;
Eko tir' ogo mi'
mf Sugbon e ma ss' eyi titi,
K' e ma fi ranti mi.
Amin.
506
S.M. & Ref.
Nitori eyi li eje mi tin majemu ti tun, ti a ta sile fun opo o nla fun lmukuro ese. Matt
26:28.

1. mf I sin dapo mimo


Ore-ofe l' o je
K'a je akara, k'a mu wain'
N' iraanti Re Jesu.
Fun ranti' ebo mimo na,
Mimo na, mimo na,
L'awa pejo po fun l' oni
Lali f' iku Oluwab han
Titi oun------ Y;o fi de;
Od' lnu ijoba Baba mi;
Ki nlo tun ba yin mu;
N' iru' dapo be ao ri idande gba

N'gba ba ro m' eje na,


Ogun esu le nde,
A o segun gbogbo won,
Nipa eje Jesu,
Odagutan.

2. Eje ti nsan f' ese


L' ar' apere re yi;
Eri si ni li okan wa
Eri lwo fetan wa.

3. A!eri die yi,


Bi o ba dun to loke orun
N'gba t' a bar' oju Re.

4. Gbana ao mo daju
Pe aworan Re ni wa;
Gbogb' ona ore' yanu Re
Nkede titi aye. Amin
507
8.8.8.6.& Ref.
Wo o, awa li fi gbogbo re sile Matt. 19:27

1. mp M o f' aye at' ife mi fun.


Od'agutan t'o ku fun mi;
Je ki nle je olotito
Jesu Olorun mi.
p Un o wa f' Eni t' o ku fun mi,
Aye mi yo si dun pupo,
Un o wa f' Eni t' o ku fun mi,
Jesu Olorun mi.

2. cr Mo gbgbo pe Iwo ngba ni,


Tori' Wo ku, k' emi le laa;
Emi y'o si gbekele O,
Jesu Olorun mi.

3. mp Iwo t'o ku ni Kalfari


Lati so mi d' ominraa;
Mo yara mi s' oto fun O,
Jesu Olorun mi.
Amin
508
L.M
Bikosepe eniyan ba je aaraa Omo enia,ki eniyan ki o si mu eje Re. eniyan ko ni iye ninu
nyin. Jn. 6:33

1. mp Jesu a teriba fun O


A mo p' o mu oro Re se
A gbo ohun Re a si si
Okan wa lati gba O si.

2. cr Wole wa, Alejo orun


Layo si ohun t' o fun wa
Ba wa je ninu ebun Re
So okan;' kanu d' ile Re.

3. Jo tewogba adura wa
K' o si gba ebo iyin wa
F' omije wa s' iranti Re.
Simi n'nu ' fe 'rapada Re.

4. mp K' a joko labe iji Re


Pe wa l' ore at' olufe
Je k' a je k'a si mu lofe
K' a ni 'telorun lodo Re

5. mp Je k' je ninu ore Re


K' a jeran Re k' am' eje Re
Ohun mio li ara Re.

6. mf Gbagbo nf' onje orun bo wa


L'o nfi ore ofe to wa
A nfi O s' onje lokan wa
A mo pe orun mbe n' nu Re.
Amin
509
11.10.11.10.
Sugbon ki olukuluku nyin ki on eran ya re be gege bi On tikara re. Efe. 5:33

1. mf Ife pipe, t'o tayo ero eda,


Niwaju Re l'a wole l'adura
Pe, ki ife ailopin le je t' awon
Ti iwo so d' okan titi aye.

2. mf Iye pipe, ma je igbagbo ododo;


Fun ireti on emi ifarada.
Pelu' fokantan lai beru iku.

3. cr Fun won l' ayo ti nbori ibanuje


Fun won l'alafia ti nm' aye dun,
Titi owuro ologo y'o fi mo
; Amin
510
7.6.7.6
Olorun si sure fun won Gen. 1:23

1. mf lre t'a su ni Eden


N'igbeyawo ' kini;
Ibukun t'a bukun won
O wa sibe- sibe.

2. Sibe titi di oni


N'igbeyawo Kristiani;
Olorun wa l' aarin wa,
Lati sure funwa.

3. I re ki won le ma bi
Ki won ko si ma re;
Ki won ni 'dapo mimo
T' enikan k' yo le tu.

4. p Ba wa pe,Baba orun,
F' obinrin yi f' oko;
Bi o ti fi Efa fun
Adaml' ojo ' kini.

5. p Bawa pe, Imanueli


cr Si to owo won poo;
B' eda meji ti papo;
L' ara ijinle Re.

6. p Ba wa pe, Emi mimo;


cr l' ibukun Re fun won;
Si se won ni aseepe
Gege b' O ti ma se.

7. mf Fi won s' abe abo Re


K' ibi kan ma boo won;
Gba won npara ile Re
Ma toju okan won.

8. Pelu won loj' aye won


At' oko at' aya;
Titi won o d' odo Re
N'ile ayo I' orun.
Amin
511
8.6.8.4.
Simi ninu Oluw, ki o si fi suru dduroo de E. OD. 37:7

1. mp Simi le Oluwa-Egbo
Orin duro orun;
cr Simi le ;fe Re ailopin;
p Si duro je.

2. mp Simi, Iwo oko t' ogbe


Iyawo re loni;
Ninu Jesu, yawo re ni
Titi aye.

3. mp At' iwo ti a fa owo re


F' oko n' nu ile ti;
Simi, Baba f' edidi Re
Si eje yin.

4 mf E simi eyin oro won.


To wa ba won pe ,lo;
Olorun won ati ti yin
Gba ohun won.

5. Simi; Jesu oko ijo


Duro ti yin nihin,
Ninu idapo yin, O nfa
p ijo mora.

6. mp E simi Adaba mimo,


M'oro Re se n' nu wa
cr Simi le 'fe Re ailopin;
p Si duro je.
Amin
512
7.6.7.6.D.
Ohun ti Olorun ko so sokan, ki enia kio mase yo won. Mat.19:6

1. mf Baba, Eleda gbogbo,


Ninu ogbon Re nla;
Lo so awon meji po
Ninu ogba Eden;
f Fifun awon 'mo Re yi;
Ife atorun wa
K' ibukun wa n'ile won,
ile t' Olorun ngbe.

2. mp N' igbeyawo Galili,


Iwo ba won pejo
Jo, sokale s' arin wa,
Bukun oko, aya;
cr So ikore di adun,
So ekun di erin.
Ko won lati mo O li
Onise iyanu.

3. p Emi orun alaye,


Mi si won lat' oke;
Fun won ni iwa- mimo,
Fun won n' ife pipe,
Jo, ma se amona won,
Ki won le sa f' ese
Se akoso aye won,
Li won le dabi Re,

4. cr B' iwo ko ko ile na,


Wahala asan ni;
B' Iwo ko si n' ile won
Asan ni aye won;
mf Sugbon ile t' lwo wa
Idapo didun ni;
Biti ife Re ba wa;
Ife ailopin ni
Amin.
513
8.8.8.6.
Beni Olorun nla enia t' abo, o ti sure fun nwon Gen1:27 & 28.

1. mp O lorun ife, a juba,


Gba' dura awon meji yi,
Gba ' dura awon meji yi
Ti ao po l' okan, l' ara
Mu won fe' kan n' nu l' kan n'nu' Re.

2. mf Gbati gbogb' ojo kun f' ayo


Ati imole t' ona si gun
Nipa igbagbo ni nu Re

3. p 'Gbat' igbi ' danwon'bi lu won


T'o dabi pe gbogbo re pin,
Ni gbigbekele O kan ,
Mu won je kan ' kan n' nu Re;

4. mf Eyi t' o je ' pin won l' aye


Ayo ni tabi ikoro,
Nipa ipa, or' ofe Re
Mu won je' kan n' nu Re.

5. f Ife ailopin, wa won gbe,


Je alabo won titi lae
N'tori k'u kole pin n' nu laiya
Awon t' lwo so po.
Amin.
514
7.6.7.6.
Olorun, Olorun wa tikalarare yio bu si fun wa. OD. 67:6.

1. mp A gb' okan at' ohun wa


Si Baba Eleda
Ni' awon ranse Re yi
Ni iyin at' a d ura.

2. mp Ayo fun ' fe t' a f' eeysan


Ati ayo t' oke;
Yin fun 'bukun ainniye.
Ife t'o ta fe yo.

3 mp Adura ki ; dapo yi
Le je ewyi t' o pe;
k' ife won le je okan,
K' won si j' okan .
Ife t' ta okan nu' Re.

4. Adura k' o asepe


ile won oni;
Si mukun oj' aye won
Ti ao ma ri titi.

5. f Iyin fun' reti ogo


T'o gaju orun lo;
Biti gbagbo y' o fo lo,
Ti fe y'o wa titi
Amin
515
7.7.7D.
Nitori eyi li okunrin yio se fi baba atai iya re sile, on o si dapo mo aya re.Efe. 5:31

1. mf Oluwa , fase Re si
Idapo t' anjeri yi;
F'' ola Re ba wa pejo,
F' ileri fe won mimo
So ‘dapo yi di mimo
Fun won ati lodo Re.

2. mf Wo farahan ni Kana
N' igbeyawo bi eyi;
Ba wa pe nihinyi,
cr Wo orisun ibukun;
Fi ayo t' aye ko ni
Se gbeyawo yi l' oso.

3. mf A ko fe ise yanu,
Pe ki omi di waini;
Gbogbo ife okan wa
Ni, k'a to ife Re wo;
K' agbara lat' oke wa
So ' fe di mimo.

4. mf Lat' oni lo, Oluwa,


Jek’ ajo t'oko t'aya,
B' o ti le wu k' o gun to,
De opin li odo Re;
cr Ni ile isimi mi,
f Ni ile li orun.
Amin.
516
6.6.4.6.6.6.4.
Ko dara ki okobinrin na ki o nikan ma gbe emi o se ohuranlowo ti o dabi re fun u. Gen
2:13

1. f Kristi n' nu' ogba, Eden,


L'a gbe ti r' ase yi,
Ase Tire,
P'o ye mi jo eni meji
Ki won jo ma rin po
Niu aye.

2. mp Nje a k' ara wa jo


Lati se ase yi
T'ojo kini;
p Jo ma sokale,
K'o wa si arin wa,
Pelu ibukun Re;
Sokale wa.

3. mp K'awon mejiji yi,


T' a fe lati so po,
Le wa fun O.
N'gbagbo ma ko won
N’ise won s’ara won,
Ki won si le repo,
Tit' aye won
Amin
517
C.M
A si pe Jesu ati awon ehin re pelu ibi iyawo.Jn 2:2

1. mf N' ilu kana ti Galilii,


Nit' ase' agbeyawo,
Jesu f' ara Re han nibe,
Pel' awon 'mo-ehin.

2. p Jesu masai f' ara Re han


Nibi' gbeyawo yi,
K'o si fi ibukun Re fun
Oko ati aya.

3. p Jeki won le wa n'irepo,


Ni ojo aye won;
K' ife at' orun wa so won,
K'aye ma le ja won.

4. p Ki won ma ran ‘ra won


Nipa a ojumose;
Fi alafia Re kun won.
Fun won n' itelorun.

5. p Gege b' ire kini,


Ni ogba Eden!
Ki won ma bi wa o mi re
Ti' opin emi won!
Amin
518
C.M
A si pe Jesu ati awon omo ehin re pelu si ibi igbeyawo Jn 2:2

1. mf Jesu f' ara han nitoto


Nibi ase' yawo
Oluwa, awa be o wa
F' ara Re han nihin

2. Fi ibukun Re fun awon


Ti o da ' wopo yi;
F oju rere wo' dapo won,
Si bukun egbe won.

3. F' ebun ife kun aya d' okan


Fun won ni telorun;
Fi alafia Re fun won,
Si busi ini won

4. F' ife mimo so won d okan


Ki won f' ife kristi
Ma aniyan fere;
Nipa ajumose.

5. Je ki won ran won lowo


Ninu igbagbo won ;
Ki won si omo rere,
Ti y o gbe le won ro
Amin
519
6.5.6.5
Iwo o dubule, orun re yio si dun, Owe.3:24

1. mp O jo oni lo tan
Orun sunmole’
Okunkun ti de na ,
Ile si ti su.

2. Okunkun bo ile,
Awon 'r'awo yo;
Eranko at' eye
Lo ni' bukun won

3. mf Jesu f' orun didun


F' eni alare;
p Je ki ibukun Re
P'a oju mi de,

4. cr Je k' omo kekere


La nla rere;
S' olo ko t' ewu nwu
Ni oju omi.

5. p Ma toju alasian
Ti ko r' orun sun;
mf Awon ti nro ibi
Jo, sa won l' ekun.

6. p N'nu gbogb' ewu oru,


Li k' angeli Re
Ma se oluso mi
Lori 'busun mi

7. mp Gba' ile ba si mo
Je k' emi dide
f B'omo ti ko l' ese
Ni iwaju Re

8. ff Ogo ni fun Baba,


Ati fun Omo,
Ati f' Emi mimo,
Lae ati laelae.
Amin
520
C.M
Omo na si ndgba, o si nlagbara Lk2:40

1. mf Bi osun gbege eti 'do,


Tutu mini- mini,
B' igbo dudu eti omi,
B' itana ipado.

2. Be l' omo na yoo dagba


Ti nrin l' ona rere;
T' okan re nfa si Olorun
Lat' igba ewe re.

3. di Ewe tutu l' eba odo


p B' o pe , a re danu;
Be n' itana ipa omi
Si nre l' akoko re.

4. cr Ibukun ni fun omo na


Ti nrin l'ona Baba;
f Oba ti mimo laelae.

5. mf Oluwa ,Wo l' a gbekele,


Fun wa l' ore- ofe;
cr Pa wa mo b' omo Re.
Amin
521
6.5.6.5.
Tani ha ojo ohun kekere Sak. 4:10

1. mf O po ikan omi,
Yanrin kekere,
Wonyi l' od' ohun nla
At' ile aye.

2. mp Iwa wa kokan
Ti a ko si
cr L'o nd' odun aimoye
Ti ainipekun.

3. mp Iwa ore die,


Oro 'fe die,
cr L'o ni' aye di Eden
Bi oke orun.

4. p Isise kekeke
L'o nm' okan sina,
Kuro l' ona ere
Si ipa ese.

5. mf Ise anu die


T' a se l' omode
cr Di bukun l' orile
To jina rere.

6. f Awon ewu l' ogo


nigberka angeli;
Se wa ye, oluwa
p F' egbe mimo won.
Amin.
522
11.11.11.11.
Emi li Olusoagutan rere. Jn 10:11

1. mf Oluso-agutan l' olugbala wa,


B'a ba wa l' aya Re kil' a o beru,
Sa je k'a lo s’ibiti O nto wa si,
Ibaje asale tab' oko tutu.

2. Oluso-agutan awa m' ohun Re


p W'o b'oro kele Re ti nm' okan wa dun;
B'o tile mba wa wi jeje l' ohun Re,
Laisi Re l'ehin wa awa o segbe.

3. p Oluso-agutan ku f' agutan Re,


cr O f' eje Re won awon agutan Re
O si fi ami Re s' ara won, o ni;
'Awon t' o l' Eni mi, awon ni t' Emi'.

4. mf Oluso-agutan, l' abe iso Re,


Bi koriko ba wa ,ki y'o le nkan;
p Bi awa tile nrin l' oojiji iku,
A wa ki y;o beru, awa o seun.
Amin
523
6.5.6.5.
E o si mo otito, otito yio ssi nyin di Ominira. Jn .3:32.

1. mf Jesu Onirele,
Omo Olorun,
Alanu, Olufe,
p Gbo' gbe Omo Re.

2. p Fi ese wa ji wa.
Si da wa n' ide,,
Fo gbogbo orisa,
Ti mbe l' okan wa.

3. f Fun wa ni Omnira,
cr F' ife s' Okan wa;
Fa wa, Jesumimo
S' 'ibugbe l' oke.

4. To wa l' onaa ajo,


Si je ona wa
La okun aye ja
S' imole orun.

5. mf Jesu Onirele,
Omo Olorun,
Alanu, Olufe,
Gbo' gbe Omo Re.
Amin.
524
7.6.8.6.
E si maa ko eko lodomi , nitori oninu tutu ati oonirele okan li eni Matt :

1. mf M o fe ki ndabi Jesu
Ninu lwa pele;
Ko s' eni gb'oro'binu
L'enu Re lekun ri.

2. Mo fe ki ndabi Jesu
L' adura 'gba gbogbo;
p Lori oke ni on nikan
Lo pade Baba Re.

3. mf Mo fe ki ndbi Jesu
Emi ko ri ka pe;
Bi nwon ti korira Re to
K'o s' enikan ni bi.

4. Mo fe ki ndabi Jesu
Ninui ise rere;
K'a le wi nipa t' emi pe
'O se' won t' o le se.

5. Mo fe ki ndabi Jesu
T'o f'iyonu wipe;
'Je k' omode wa s' odo mi'
Mo fe ipe Re.

6. p Sugbon nko dabi Jesu,


O si han gbangba be;
cr Jesu fun mi l' oore-ofe,
Se mi, ki ndabi Re.
Amin
525
7.7.7.7
O gbe Owo Re le won oo ssi suure fun won Mk,10:16\

1. mf Jesu fe mi, mo mo be,


Bibeli l' o so fun mi;
Tire l' awon omode
f Won ko l' agbara on ni.

2. p Jesu fe En't' O ku
Lati si orun sile;
mf Yio we ese mi nu;
Je ki omo Re wole.

3. p Jesu fe mi sile si,


Bi emi tile aisan;
L'or' akete aisan mi
cr Y'o t' ite Re wa so mi.

4. mf Jesu fe mi y'o duroo


Ti mi ni gbogb' ona mi.
'Gba mba f' aye yi sile,
Y'o mu mi rele Orun.
Amin.
526
8.6.8.5.&Ref.
Nwon o si je temi, li Oluwa awon omo ogun ori,
Liojo na nigbati mo ba nsiro oso mi.Matt 3:17

1. mf ’Gbat' Oba de' gba t' o ba de


Lati sir' oso Re
Gbogbo oso Re iyebiye,
f Bi irawo owuro , won ns' ade Re loso
Ewa wn oyo pupo, ewa f' ade Re.

2. mf Yio ko jo , yio ko jo,


Oso ijoba Re;
Awon mimo, awon didan
A won ti O fe,

3. mf Awon ewe, awon ewe


T'o fe Olugbala ;
Ni oso Re iyebiye,
Awon ti O fe.
Amin.
527
8.7.8.7.7. 7
A si bi Jesu ni Bethlemu,ti Judea.

l. mf `Nigba kan ni Betlehemu


Ile kekere kan wa,
Nib iya kan te' mo re si,
Lori ibanuje eran;
Maria n' iya omo na,
Jesu Krist’ si l’omo na,

2. Ot' orun wa s' ode aye,


On l'Olorun Oluwa;
O f' ile eran se ile
'Buje eran fun buusun;
Lodo awon otosi,
Ni Jesu gbe li aye

3. Ni gbogbo igba ewe Re .


O ngboran, O si mbo' ota ;
O feran , O si nteriba ,
Fun iya ti ntoju Re!
O ye ki gbogb' omode
K' o se olugboran be

4. Tori On je awose wa,


A ma dagba bi awa ;
O kere ko le da nkan se,
p A ma sokun bi awa;
O si le ba daro,
f O le ba wa pelu.

5. Ao f' oju wa ri nkehin.


Ni agbara ife Re;
Ni tori omo rere yi
Ni Oluwa wa l'orun;
O nto awa omoRe
S' ona ibiti On lo.

6. f Ki se ni ibuje eran
Nibiti malu njeun
L' awa o ri, sugbon l' orun
'Gba won ' mo Re b' Irawo
Ba wa n' nu aso ala.
Amin

528
8.6.7.6.7.6.7.6.
Ti nyin gbogbo won, eniyan ni ti kristi. 1 kor. 3:22&23

1. mf O re kan mbe fun Omode


Loke orun lohun;
Ore ti ki yi pada,
T ife Re ko le ku;
p Ko dabi ore aye
Ti mbaje l' ododun;
f Ore yi ye lati je
Oruko Re owon

2. mp Isimi kan mbe f' omode


Loke orun lohun;
F' awon t' o f' Olugbala
Ti nke ' Aba Baba'
di Simi lowo iyonu,
Low' ese ati ewu;
Nibi awon omode
p Y'o simi titi lae.

3. mf Ile kan mbe fun Omode


Loke orun lohun ;
f Nibiti Jesu njoba
Ile alafia!
di K'o s' ile to jo l' aye
T' a le fi s' akawe;
f Ara ro 'lukuluku;
Irora na d' opin

4. cr Ade kan mbe fun Omode


Loke orun lohun;
Eni t' o ba nwo Jesu,
Y'o ri ade na de;
Ade t' o fi fun gbogbo
Ti y'o fi fun gbogbo
mf Awon t' o wa oju Re
Ti won si fe nihin.

5. f Orin kan mbe fun Omode


L'oke orun lohun;
Orin tiko le su ni,
B' o ti wu k'a ko o!
mf Orin t' awon angeli
Ko le ri ko titi;
Krist' ki s' Olugbala won
Oba l'o je fun won.

6. f Ewu kan mbe fun Omode


Loke orun lohun;
Harpu Olohun didun!
Imo ' pe isegun;
Gbogbo ebun rere yi
L'a ni ninu Jesu;
p Ewa eyin omode,
Ki won le je ti yin.
Amin.
529
6.6.6.6.8.8
Ma wi, Oluwa, nitori iranse Re ngbo. 1 sam.3:9

1. mf Gbati samuel' ji
To gbo ohun Eleda
Ni gbolohun kokan,
Ayo re ti po to!
Ibukun ni f'omo t'o ri
Olorun nitosi re be.

2. B' Olorun ba pe mi
Pe, on li ore mi;
Ayo mi y'o ti to,
Un o si f' eti sile;
B' Olorun sunmo 'tosi be.

3. Ko ha ni soro?
Beni, n ' nu oro Re
O npe mi lati wa
Olorun samuel,
N'nu iwe na ni mo ka pe
Olorun samuel npe mi.

4. Mo le f' ori pamo


S' abe itoju Re;
Mo mo p' Olorun mbe
L'odo mi n' gbogbo;
O ye k' eru ba mi
N'tor' Olorun sunmo 'tosi.

5. Gba mba nka oro Re,


Ki nwi bi Samuel pe
'Ma wi, Oluwa mi
Emi y'o Tire;
Gba mo ba si wa nile Re,
Ma wi, tori' ranse Re Re ngbo
.Amin.
530
C.M
Nitori ibi hiha li enu ona na ati toro
loju ona ti o lo si ibi iye matt 7:14

1. mf O na kan lo ntoka s' orun,


Isina ni yoku
Hiha si l' oju ona,
Awon kiristian lo fe.

2. Lat' aye o lo tarata


O si la ewu lo;
cr Awon ti nfi gboya rin la,
Y'o d' orun nikehin

3. mf Awon ewe yo ha ti se
Le la ewu yi ja;
Tori idekun po l' ona
F' awon odomode.

4. p Gbigboro l' ona t' opo nrin


O si teju pelu
Mo si mo pe lati d' ese
Ni won se nrin nibe.

5. mf Sugbon kese mi ma ba ye
Ki nma si sako lo;
Oluwa jo s' oluto mi,
Emi ki o sina.

6. Nje mo le lo lasisi' foya


Ki ngbekel' oro Re
p Apa Re y'o s' agutan Re
Y'o si ko won dele.

7. cr Beni un o la ewu yi ja
Nipa itoju Re;
f Un o tejumo' bode orun
Titi un o fi wole.
Amin
531
C.M
Nwon ti fo ao isgunwa won nwon si so won di funfun ninu eje Odo-agutan,Ifi. 7:14

1. f Y ika or'ite Olorun


Egberun ewe wa;
Ewe t' a dari ese ji,
Awon egbe mimo.
Nkorin ogo, ogo, ogo.

2. Wo olukuluku won wo
Aso ala mimo;
Ninu imole ailopin
At' ayo ti ki sa.

3. mf Ki l' o muwon de aye na,


Orun t' o se mimo;
cr Nib' alafia at' ayo,
Bi won ti se de be.

4. p Nitori Jesu ta' je Re


Lati k' ese won lo;
A ri won ninu eje na,
Won di mimo laulau.

5. mf L' aye won wa Olugbala,


Won fe oruko Re;
cr Nisisiyi won r' oju Re,
Won wa niwaju Re

6. p Orisun na ha nsan loni?


Jesu mu wa be;
cr K'a le ri awon mimo na,
f K' a si ba won yin O.
Amin
532
L.M
Kristi jiya lekan nitori ese wa, olotito fun alasioto ki o le mu wa de Odo Olorun 1 Pet.
3:18

1. mf Jesu t' o wa l'oke orun


p Sokale d' eniyan, O ku;
Ninu Bibeli l' a le ri
Bi On iti ma se rere.

2. O nkiri, O si nse rere


O nla ju awon afoju;
Opo nwon t' o si yaro
O sanu won, O si wo won.

3. Ju wonni lo, O ku buru;


Ohun wonni t' Olorun fe;
O si se eni t' o tutu;
Yoo si gbo t' awon ewe.

4. p Sugbon iku t' O ku buru;


A fi ko or' agbelebu
Owo rere t' o se nkan yi,
p Won kan mo 'gi agbelebu.

5. p Be l' O ku nitori yi na,


Od' eniyan, ko ba le ku;
Bibeli ni O t' orun wa,
K' o le dari ese ji ni.

6. O mo b' eniyan ti buru,


O mo b' iya ese ti ri
Ninu anu, Jesu wipe.
On o gba iya ese je.
Amin
533
L.M
O mu isu akara marun ati eja meji, O gbe oju soke, O sure, o si buu, o si fi fun awon
omo ehin Re,. Mk6:41

1. mf W a, ba wa jeun, Oluwa
Je k'a ma yin oruko Re;
cr Wa bu si onje wa, si je
K'a le ba o jeun l'orun.
Amin
534
L.M
Gbogbo eda Olorun li o dara bi a ba fi ope gba a 1Tim. 4:4.

1. f A f' ope fun O, Oluwa


Fun onje wa, at' ebun mi;
di Onje iye lat' oke wa.
Amin
535
S.M
E sunmo Olorun On yio si sunmo yin.Jak4:8.

1. f Jesu a w' odo Re.


L'ojo Re mimo yi.
To wa wa b' awa ti pejo.
Si ko wa fun 'ra Re.

2. p Dari ese ji wa,


Fun wa l' Emi mimo;
Si ko wa, k'a lo aye wa
K' a le ye' bugbe Re.

3. f F' ife kun aya wa,


Bukun oluko wa;
K'awa at' awon le pade
Niwaju Re l'oke.
Amin.
536
C.M
O miran si boi si ile rere, o si so eso Mat. 13:8

1. mf K' awa to pari eko wa,


Awa f' iyin fun O;
Tori ojo Re mimo yi,
Jesu ore ewe.

2. f Gbin oro Re si okan wa,


Gba wa lowo ese.
Ma je k'a pade l' ehin Re,
Jesu ore ewe.

3. Jesu, jo bukun ile wa;


K'a lo ojo yi re;
K'a le ri aye lodo Re;
Jesu ore ewe. Amin.
537
6.5.6.5.
Ko juja si esu, on a si sa kuro lodo nyin Jak. 4:7

1. mf Mase huwa ese;


Ma soro' binu;
Omo Jesu l'ese
Omo Oluwa.

2. mf Krist' je oninure,
At' Eni mimo ;
Be l' awon omo Re
Ye k' o mimo.

3. p E ma ibi kan wa
T'o nso irin re;
O si n fe dan o wo
Lati ba ibi.

4. E ma se gbo tire,
B'o ti le soro
Lati ba esu ja
Lati se rere.

5. mf Eyin ti se leri
Ni omo owo;
Lati k' esu sile
Asi ona re.

6. om' ogun krist' niyin,


E ko lat' ba
Ese inu yin ja,
E ma se rere,

7. f Jesu l' Oluwa yin,


cr O se Eni re;
Ki eyin omo Re
Si ma se rere.
Amin
538
C.M
Awon omode si nke ninu Templi wipe, Hosnana si omo Dafidi. Matt. 21:15

1. f Hosana! eyi e korin s' oke


S' omo nla Dafidi
Pelu kerub ati seraf,
K'a yin om' Olorun.

2. mp Hosana! eyi nikan


L' ahon wa le ma ko!
cr Iwo ki o kegan ewe
Ti nkorin iyin Re.

3. f Hosana! Alufa, Oba,


Ebun Re ti po to!
Eje Re l'o je iye wa
Oro Re ni onje.

4. mf Hosana! Babaawa mu
Ore wa fun O,
Ki se wura tab' ojia
Bikose okan wa.

5. Hosann! Jesu lekan si


O yin awon ewe;
cr Sanu fun wa, si f' eti si
Orin awa ewe.

6. Jesu b' Oba ra wa pada,


T'a si wo 'joba Re;
Ao fi fere wura ko
Hosana titi lae
Amin.
539
8.4.8.4.8.8.8.4.
Ore kan si mbe ti o fi ara moni ju ara kunrin lo Owe 18:24

1. mf E nikan mbe t' O feran wa,


A! O fe wa!
Ife Re ju ti yekan lo,
A1 O fe wa;
p Ore aye nko wa sile,
B' oni dun , ota le koro;
cr Sugbon ore yi ko le ntan mi,
A! O fe wa!.

2. mf Iye ni fun wa, b' a ba mo,


A! O fe wa!
di Ro b' a ti je ni ' gbese to,
A! O fe wa!
p Eje Re l' O si fi ra wa
Nin' aginju l' o wa wa ri,
cr O si mu wa wa s' gbo Re,

3. f Ore ododo ni Jesu,


A! O fe wa!
O fe lati ma bukun wa
Okan wa fe gbo ohun Re
Okan wa fe lati sunmo;
On na ko si ni tan wa je,
A! O fe wa!

4. p Loko Re l'a nri daiji


A! O fe wa!
cr On o le ota wa s' ehin,
A! O fe wa!
f On o pese 'bukun fu wa;
Ire l'a o ma titi
ff On o fi mu wa lo s' ogo,
A! O fe wa!
Amin
540
C.M
O si gbe won lapa- O si sure fun won.Mk.10:16

1. mf W o b' olus'agutan Israel;


Ti fi ayo duro;
O npe awon Od'agutan,
O si ko won mora.

2. mp On si wipe ' je ki awon wa;


E mase k' egan won;
Lati sure fun iru won,
L' Oba angel' se wa.

3. f Pelu ope l' a gbe won wa,


A jowo won fun O,
Ayo; pe awa je Tire
k' omo wa je Tire
Amin
541
7.7.7.7
Nbe l' Oluwa gbe pase Ibukun, ani iye laelae O.D 113:3.

1. mf Baba orun, k' ife Re,


Tan s' ori wa lat' oke;
Je k' omo yi ni ipo
N' nu majemu ore Re

2. cr Ba wa pe, si gb' adura


Jesu. omo Olorun
K' eje Re, ti Kalfari
W ese ibi omo yi.

3. mp Emi mimo sokale,


Ya omo yi si mimo;
Fi agbara nla Re han,
S'amona re titi opin.

4. mf Jehofa, Baba, omo,


Eni meta, Okan so;
K' ibukun t' odo Re wa,
Tire ni gbogbo ogo
Amin.
542
6.7.8.6.8.8.11.
E je ki awon omo Kekere aw sod
o mi Lk 13:16.

1. mf Gba won iya salem


Gb' omo won to jesu wa;
Awon om' ehin Re le won
Sugbon ki won to ma salo
f Krist ri won. o f' ayo ipe;
Je ki awon omo wewe to mi wa.
2. mp Em' o tewogba won.
Un o gbe won mora pelu;
Emi y'o Oluso won,
E mase le won lo;
Bi won, ba f' okan fun mi,
f Won y'o ba gbe' nu ogo.
Je ki awon omo-ewe to mi wa,

3. mf Olugbala wa seun;
T' o tewogba' won mo na;
Sugbon opo ewe mbe ti
Ko gbo Oko ka re ri,
Ti won ko ka so Bibeli ri,
mp Nibit' Olugbala so pe;
Je ki awon omo-ewe to mi wa,

4. cr Laipe, ti keferi
Ti mbe ni gbogbo aye
M' oro Re se, ki won si ko
Orisa won danu;
Jo tan imole Re si won,
f Farahan b' Olorun ife.
Ko awon 'mo-ewe lati to O wa.
Amin
543
6.5.6.5.
E je ki awon omo kekere ki o wa sodo mi ,E ma si se da won lekun. Mk. 10:14

1. mf Jesu, t' opo logo,


Jo, deti sile;
Gbo yin awa ewe,
B' a ti njuba Re.

2. B' o ti je mimo to,


Olodumare,
Wo y'o teri sile
Gba t'a ba yin O,

3. p Omode l' awa je,


A ko pe sako;
Olugbala,to wa
Si ona orun.

4. cr Gba wa lowo ese;


So wa lojojo;
Jek' a le feran Re
Ko ese walo.

5. f Gbat' O ba si pe wa
S' ile wa orun;
Layo l'ao dahun pe;
Oluwa, a de!
Amin.
544
10.4.10.4.10.10.10
Ko mi li ona Re Oluea , ki O si to mi li ona otito O.D 27:11

1. mp Jesu, wo t'o npe omde mora,


Mo wa sodo Re;
Jo di mi mu, k'o si ba mi soro
Sin mi rele;
Ki nma ba ya kuro lona iye,
K' agutan Re ma di ije f' esu.

2. Mo feran ranti p' ese mimo Re


Ti rin -na mi.
L'opopo aye at' ona hiha
Pe l' Olorun
Pe O muyon ri l' aya maria,
Pe O si jije f' awon obi Re.

3. cr Jesu Onrele, Jek' Okan mi


T'o kun f' ese
Di mimo, latilabawon, bi Tire,
Si ma gbe' be
Gbana nu o mo Olorun Baba mi
Un o ma gberu l' ogbon at' agbara.

4. f Olugbala , Wo ni un o korin si
Li owuro,
Iyin y'o igba' banuje mi
D' igba ayo;
Ninu se ati ninu rere mi,
Fe re y'o ofin at' ayo at' ayo mi.
Amin.
545
7.7.7.7
Jesu si pe omoi kekere kan sodo Re mak.10:2

1. mp Jesu, Wo onirele,
Wo mi , emi omode;
Jo sanu aimokan mi,
Jek' emi wa sodo Re.

2. di Mo fe k'a mu mi O wa;
Oluwa, mase ko Mi;
F' emi omode l' aye
N' ijoba or- ofe Re.

3. mp O wu mi ki ndabi Re;
Fun mi l' okan igboran;
Wo Alanu, Olore,
F' nwa f' ogo Re fun mi.

4. Leke gbogbo re, Jesu.


Je nma se fe Baba mi
Ki nma b' Emi Re n' inu
Ki nwa f' ogo Re nikan.

5. cr Odagutan Olorun
Wo ni k'o japere mi.
Iwo tutu, Wo tenu;
O si ti s' omode ri.

6. mf Jesu, ore Omde


Ni owo Re ni mo wa;
Se mi gege b' o ti ri
Si ma gbe' nu mi sin O.

7. f Emi y'o fi tin Re han


Un o fi aye ni mi sin O.
Aye y'o si ri Kristi,
Omo mimo ninu mi.
Amin.
546
7.8.7.8.8.
Jesu si wipe ' e je ki awon omo kekere wa si odo m, Nitori ti iru won ni ijoba Olorun, O si
sure fun won mk. 10: 16

1. mf Jesu nihin l' a duro


Lati se bi Iwo ti wi;
Omode yi, ni ase Re
L'a fi bun O nisisiyi;
Kristi li a fun l' omo na;
Iru won n' ijoba Orun.

2. mp Fun eyi a to wa
Gba omo yi ti a mu nihin,
Ni anu seni omo Re;
Ma si se fi sile laelae
L'aye ati l'orun pelu.

3. cr L'aya Re l' omo yi wa


Isura owon f' okan wa,
Je k' adura wa goke,
Y'a ibukun Re l' aniwon.
Si ko oruko ti a fun
Omoi yi sinu we iye
Amin.
547
C.M
Awon omode nke ni templi lo wipe, Hosana. Mat. 21:15.

1. mf Gba Jesu wo templi lo,


Ohun iyin l'a gbo;
Omode jewo eto Re,
Gbogbo won si nyo si ;
2. ff Hosana mu templi ro,
Ahon pipo danu;
Hosana si Oba t' Orun,
S' iru mimo Dafidi.

3. Oluwa ' sojo wa d' otun,


Gbat' Omode yin O;
Agbara ast' ore Re po
Bi t' ojo igbani.
Amin
548
8.7.8.7
Emi ni Oluso -agutan rere Jn. 1.0:14

1. mf Jesu wo ti mbo agbo Re;


B' olus' agutan rere,
Ti sike awon t' o dera,
Ti 'gb awon odo mora.

2. mp Jowo! gba omode wonyi,


F' aanu gba won mo aya,
Gbangba l' o daniloju pe,
Ewu ki y;o le pa won n' be.

3. Nibe, won ko ni sako mo,


Ekun ki y'o le pa won;
Je ki ' ronu ife nla Re
Dabo won l' ona aye.

4. N' nu papa Re oke orun,


Je ki won ri' bi' simi,
Ki won j' oko tutu yoyo,
Ki won m' omi ife Re.
Amin.
549
C.M
Iwo Olorun ninu ore Re li o ti npese fun awon talaka O.D. 68:10

1. mf Olorun, ite ogo Re,


Yio wa titi lae;
Obi wa, talaka ni won,
F' ibukun Re fun wa.

2. O wu O ni, lati se wa
p Ni talaka; sugbon
Maa se alabojuto wa,
Gba ti a wa l' aye.

3. A mo, b' atile je Tire,


T' a j' oruko mo O,
A j' alejo; sugbon se wa
L' omo asayan Re.

4. Oluso agutan wa, wo


Agbo kekere Re;
F' ogo at'opa Re to wa,
Omo agbo Tire.
Amin.
550
8.7.8.7.D.
Lati enu awon Omo-owo, ati omo- omu, ni iwo ti se agbara. OD.8:2

1. mf Jehofa! Olorun ogo,


Je ki omode yin O;
p A wole n' irele fun O
Ore Re ni orin wa,
Ogun Seraf' dapo gberin
Ife Re l' oke orun;
Olorun ogo, gbo tiwa,
B' a ti nyin oruko Re.

2. Imanueli Iwo t' a bi,


p T'a si fi ko or' igi,
O pe omode kekere,
Lati wa si odo Re;
Oluwa, b'o ti pe, a de.
Je k' a ri aanu Re, gba!
K' awa, pel' awon omo Re,
K'a sin O k'a si fe O.

3. A ba le wa, k' a si fe O,
K' a si beru Re l' aye;
Nikehin, k'a wa pelu Re,
f K' a ri O k'a si yin O,
Jesu ! Olorun itunu,
Olori ore dide,
f Jo tewogba orin wa.
Amin.
551
L.M
E fi iberu sin Oluwa. O.D 2:11

1 mf Omode, e sunm' Olorun,


p Pelu irele at' eru;
Ki ekun gbogbo wole fun
Olugbala at' ore wa.

2. mf Oluwa, je k'anu Re nla,


Mu wa kun fun ope si O;
Ati b' a ti nrin lo l' aye,
K' a mu ri opo anu gba.

3. Oluwa! m' ero buburu,


Jinna rere si okan wa;
L'ojojumo fun wa l'ogbon,
Lati yan ona tooro ni.

4. p Igba aisan, at' ilera


Igba aini tabi oro;
pp Ati l' akoko iku wa,
f Fi agbara Tire gba wa.
Amin.
552
4.4.8
Ojo nlo, ojiji ojo ale na jade.Jer.6:4.

1. p Oj' oni lo,


Jesu Baba,
Boju Re w' emi yi mi ka.

2. Wo Imole,
Sa toju mi;
Tan imole Re yi mi ka.

3. Olugbala,
Nko ni beru
Nitori O wa lodo mi.

4. Nigba gbogbo
Ni iju Re
Nso mi, gbat' enikan ko si.

5. Nigba gbogbo
Ni eti Re
Nsi adura omode,

6. Nitorina
Lati foya,
Mo sun, mo si simi le O.

7. Baba, Omo,
Emi Mimo
Ni iyin ye l' orun l' aye.
Amin
553
C.M.
E korin si Oluwa. O.D.96:2

1. E dide ki a si korin,
K'a yin Oluwa wa,
K'a si dupe li owo Re,
F' anfani idasi,

2. f E dide ki a si korin,
K'a yin Oluwa wa,
K'a si dupe li owo Re
Fun oro mimo Re,

3. f E dide ki si korin,
K' a yin Oluwa wa,
K' a be E fun ' rawo orun,
T'aye ko le fun ni.

4. f E dide ki a si korin,
B'a si ti fe tuka,
Ki ohun na ti a ki ko.
Le je fun rere wa.

5. f Nje gbati a ba korin tan,


T' a ba si s' or' ofe
K' ibukun Re le ba le wa.
Bi a ti nlo le wa. Amin.
554
L.M
Ranti ojo isimi lati ya si mimo.Eks. 20:8.

1. mf Leyin ' jo mefa t' O sise,


O simi ni ijo keje ,
O pase fun wa k' a se be,
Ki a si pa ojo na mo.

2. A wa lati m' ase na se,


Ninu ile Re yi loni,
Ni won' gbat' a mbenihinyi,
Jek' a mo p'o mbe lodo wa

3. p Bi ao ti s' iwe mimo Re,


Jek' a le ka pelu rele,
K'a le mo pe' Wo l' onsoro,
Ki a teti si eko Re.

4. Tumo re fun wa 'ra Re,


Alailogbon sa li awa,
Oro Re sa jinle pupo,
O ye wa ko si to fun u.

5. p Pelu awon oluko wa,


Fi fun Mimo Re fun won,
Ki O ma ko won n' itumo,
B' o ti wu k' ijinle na to.

6. Nigbat' a ba kuro nihin,


Jo masai pelu ona wa,
K'a le ma se iranti Re
Titi ojo' simi miran
. Amin.
555
10.10
Nigbana li eni- buburu ni wa,
a si mu eyi ti a fun si aiya re kuro.Mat 13:19.

1. mf Jesu Oba, a pari eko wa,


Ma jeki Esu sa l'okan wa.

2. p Jesu Oba, a s' ope lowo Re,


T'o ti fun wa li onje orun je.

3. Jesu Oba, ko s' eko bi Tire,


Ihin Re dun pupo li eti wa.

4. Jesu Oba, Iwo li ao ma wo,


O ti ko wa be ninu oro gbogbo wa.

5. p Jesu Oba, n'ijade wa lo yi,


A be O k'o dabobo gbogbo wa.

6. Jesu Oba ninu gbogb' ose yi,


p So wa, si mu wa ri ose ti mbo.
Amin
556
C.M
Inu mi dun nigbati nwon wi fun mi pe, E jeki a lo si ile Oluwa OD 122:1

1. Ile- eko ojo 'simi ,


A! mo ti fe O to!
Inu mi dun mo daraya
. Lati yo ayo re

2. Ile-eko ojo 'simi


Ore re pa poju
T;agba t' ewe wa nkorin re,
A nse afere re.

3. Ile-eko ' simmi


A wa ri ti gba,
Emi mimo Oluskoni,
L'o si nse toju re.

4. Ile eko 'ojo simi


Awa ri gba,
F' Olorun Olodumare
F' ibukun sori re.

5. Ile eko ojo 'simi


B' orun nran l' aranju,
Bi ojo su dudu lorun
Ninu re emi o wa.

6. Ile eko ojo 'simi


Mo yo lati ri O,
'Wo y'o ha koja lori mi
Loni, airi ' bukun?
Amin.
557
6.5.6.5
Fi eti si ni. Olso -agutan Israeli O.D 80:1

1. Mf OLuso agutan mi
Ma bo mi titi;
Olusagutan mi
Ma to ese mi,

2. Di mi mu, si to mi,
Ni ona hiha,
B' O ba wa lodo mi
Emi ko sina.

3. Sin mi s' ona orun,


Niojojumo,
Ma busi ngbo mi,
Si mu fe O.

4 f K' ayo tabi ekun,


Ti odo Re wa;
K' iye anipekun,
Le je ayo mi.

5. Ma pese okan mi,


Ni ojojumo;
Si je k' Angeli Re,
Sin mi lo ile.
Amin.
558
7.7.7.7
Kiyesii, awon omo ni ini oluwa; omo inu si li ere re. OD. 127
1. mf Gb' adura wa Oluwa,
P' awon omo t' o fun wa,
Pin won ninu' bukun Re,
Si fun won l' ayo l' orun.

2. Jek' okan won sunmoO,


Nigba won wa l' omode
Je ki won f' ogo Re han,
L'akoko ' gba ewe won.

3. p Fi eje Olugbala,
We okan won mo tooto;
Je k'a tun gbogbo won bi,
Ki won si le je Tire.

4. p Anu yi l'a mbebe fun,


K' o si gbo adura wa;
Iwo l' agb' okan wa le,
Ni anu gb' adura wa.
Amin .
559
S.M
A gbe awon omo-owo wa sodo re mat.19:13

1. Jesu pe omode,
O gbe won s' aya Re;
O f' owo Re gba won mora,
O si nsure fun won.

2. p Jesu gb' omode yi


T''a Re se ni Tire,
p Tikala Re se ni Tire,
K'o dagba f' ogo Re.

3. p Gb' awon omode wa,


Ti won waju Re,
pp Si pese f' awon ti ko ni,
f Sure fun gbogbo wa.
Amin
560
8.7.8.7
Bi awa ba se omo, nje a wa li ajogun Rom.8:17

1. Balogun! Olugbala wa,


Gb' omo wonyi ise Tire,
Arole iye wonyi.

2. Arewa Baba wa O run,


Mu k' awon wonyi jo O;
N'nu aworan Tire papa,
Lo won s'agbala oke.

3. Se won l' agnnigan mimo,


Omo -ogun t'o lera;
Ki won fo itegun Esu,
Ki won segun aye.

4. K' oro Re dabi oguna.


L'enu awon omo Re;
Ti y’o jo ese l’ajorun,
Ti ara ba le da sasa.

5. Pa won mo fun ' se ogo Re,


Ki won wa lailabawon;
Ko won ;lati r' agbelebu,
Lojojumo aye won.

6. Bukun ' lana yi,


Fun ire omo wonyi,
Gba won, to okan, si ma so won,
Nikeyin gb' okan won la
. Amin.
561
7.7.7.7
Iwo ki ise eru mo bikose omo Gal. 4:7

1. f E we ti oba Orun,
. Korin didun b'e ti nlo;
Korin yin Olugbala,
Ologo n'nu ise Re.

2. A lo sodo Olorun
L'ona t' awon Baba rin;
on si nyo nisisiyi,
Ayo won l' awa o ri.

3. cr Korin agbo kekere,


E o simi n' ite Re;
Ib'a pese joko yin,
Ibe si n' ijoba yin.

4. Woke, omo imole


Ilu Sion wa lokan;
Ibe n' ile wa titi,
Ibe l'a o r' Oluwa.

5. Ma sa e duro l' ayo,


Ni eti ile ti yin;
Kristi omo Baba nwi
Pe, latfoya k'a ma lo.

6. mf Jesu, a nlo l'ase Re,


A ko' hun gbogbo sile
Iwo ma j' Amona wa
A o si ma ba O lo.
Amin.
562
6.6.6.6.
Oluwa, emi nfe ibujoko Re, ibi ago ola Re. OD 26:8

1. f Olorun awa fe
Ile t' ola Re wa;
Ayo ibugbe Re,
Ju gbogbo ayo lo.

2. mf Ile adura ni ,
Fun awon omo Re;
Jesu o wa nibe,
Lati gbo ebe wa.

3. Awa fe isun Re
Nibe l' Emi mimo
Tu or ofe jade
Gegebi t' igba ni

4. Awa fe ase Re
Kil'o dun to laye?
Nib' awon oloto
Nri O ni 'tosi won.

5. A fe oro iye,
Ti nso t' alafia,
T' itunu n'nu ija
Atayo ti ki tan.

6. f A fe korin anu,
T' a nri gba l' aye yi;
cr Sugbon awa fe mo
Orin ayo t' Orun.

7. Jesu oluwa wa
mp Bu si fe wa n' ihin;
f K'a r' oju Re l'orun
K'a ba won mimo sin.
Amin.
563
L.M
Nibiti eni meji, tabi meta ba ko ara li arin won. Mat. 18:20

1. mf Jesu, ni b' eni Re pade,


Nibe, won r' ite anu Re,
Nibe, won wa O, won ri O,
Ibikibi ni le owo.

2. mf Ko'ogiri t' o se O mo,


O ngbe inu onirele;
Won mu O wa ba wa,
Gba won nlo le won mu O lo,

3. mf Olus'agutan eni Re;


So anu Re gbani d' otun
cr So adun oruko nla Re,
Fun okan ti nwa oju Re.

4. mf Je k'a ripa adua nihin,


Lati so 'gbagbo di lile
Lati gbe ife wa soke,
Lati gb orun ka' waju wa.

5. cr Oluwa Wo wa nitosi,
N' apa Re, de ti Re sile;
Si orun, sokale kankan;
Se gbogbo okan ni Tire.
Amin
564
8.7.8.7.6.7
Ojo ibukun yo si ro Esek. 34:26

1. f Oluwa, mo gbo pe, Iwo


Nro ojo' bukun kiri;
Itunu fun okan are,
Ro ojo na s' ori emi,
An' emi an emi
pp Ro ojo na s' ori mi.

2. mf Ma koja, Baba Olore,


Bi ese mi tile po,
Wo le fi mi sile, sugbon
p Je k'anu Re ba le mi
An' emi, an' emi.

3. mf Ma koja, mi, Olugbala,


Je k' emi ro mo O,
cr Emi nwa oju rere Re,
p pe mi mo awon t' o npe.
An' emi, an emi
Pe mi mo awon t' o npe.

4. mf Ma koja mi, Emi mimo,


Wo le la ju afoju,
Eleri itoye Jesu,
p Soro ase na simi,
An emi, an emi
Soro ase na simi.

5. mp Mo ti sun fonfon nin' ese.


Mo bi O ninu koja,
ff Aye ti de okan mi , jo.
p Tu mi, k'o dariji mi,
An emi, an emi
Tu mi, k'o dariji mi.

6. cr Ife Olorun, ti ki ye,


Eje krist' iyebiye,
ff Ore-,ofe alainiwon
di Gbe gbogbo re ga n' nu mi.
An emi, an emi
7 mp Ma koja mi, dariji mi,
Fa mi mora, Oluwa,
cr Gba O nfi ibukun fun f' elomi
Ma sai f' ibukun fun mi,
An emi, an emi
p Ma sai fi 'bukun fun mi
Amin
565
11.11.11.11
Iwo so di aye mimo gege bi oro Re. OD 119:25

1. mf Fun mi n'iwa mimo; igbona okan,


Suru ninu iya; aro fun ese;
Igbagbo n'nu Jesu ! ki nmo toju Re,
Ayo n' nu isin Re, emi adura.

2. f Fun mi l'okan ope, igbekele krist'


Itara l' ogo Re; reti n'n' oro Re,
p Ekun fun iya Re; rora f' ogbe Re;
p Irele n'nu danwo, fa fe mi s' orun.

3. mf Fun mi n' Iwa funfun, Iyin fun n' Isegun,


We abawon mi nu, fa' fe mi s' orun,
Mu mi ye joba Re , Ki nwulo fun O,
Ki nj' alabukunfun, Ki ndabi Jesu.
Amin
566
10.8.10.8& Ref
E ma ko gbogbo aniyan nyin le e I pet. 5:7

1. p So gbogbo' banuje re fun Jesu


Ati gbogbo aniyan re;
Dajudaju yio da n' ide,
On yio tu o ninu
mp So won fun Jesu,
So won fun Jesu,
So won fun Jesu,
On y'o gbo;
Sa gbekele ki;
O si gba A gbo;
On yio si tu o ninu.

2. mp So won fun Jesu Olugbala re


So won k'o si ri gbala re;
Mase se Jesu, mase d' oju ti,
On yio si tu o ninu.

3. cr So won fun Jesu, On ni abo re,


Lo si odo Re fun anu;
So fun Jesu ,gbogbo wo o si ri
Ore -ofe ati tunu.
Amin
567
8.7.8.7.D.
Oluwa yio ma to o nigbagbogbo. Isa 58:11

1. mf Oluso-agutan, to wa
Awa fe itoju Re
Fun wa ni ibukun t' a nfe,
Si pese aye fun wa.
Jesu mimo, Jesu mimo )2ce
O ra wa, Tire ni wa.

2. cr Tire ni wa; fi wa s' ore,


Ma se amona fun wa,
Gba agbo Re lowo ese,
Wa wa gbat' a ba sina
Jesu mimo, Jesu mimo)2ce
Je ka tete ro mo O

3. mp Wo ti leri lati gba wa


B' a tile elese;
Anu, ore agbara Re,
To fun dande elese;
Jesu mimo, Jesu mimo)2ce
Je ka tete ro mo O

4. mf Je k'a tete wa oju Re,


Je k'a tete se fe Re,
Oluwa at' Olugbala,
Fi fe kun Okan wa.
Jesu mimo, Jesumimo)2ce
Olufe, ma fe wa si.
Amin.
568
8.7.8.7 D
Ore mi li eniyan ise. Jn. 15:14

1. mp Ore wo l'a ni bi Jesu


Ti o ru banuje wa;
Anfani wo l'o po bayi
Lati ma gbadura si?
Alafia pupo l' a sonu
A si ti je rora po,
mf N'tori a ko nfi gbogbo kn
S' adura niwaju Re.

2. mp Idanwo ha wa fun wa bi ?
A ha ni wahala bi?
A ko gbodo so reti nu,
Sa gbadura s' Oluwa,
Ko s' oloto ore bi Re;
Ti o le ba wa daro
mf Jesu ti mo ailera wa,
Sa gbadura s' Oluwa.

3. cr Eru ha nwo wa l' orun bi?


Aniyan ha po fun wa?
Olugbala je abo wa,
Sa gbadura s' Oluwa;
Awon ore ha sa o ti,
Sa gbadura s'Oluwa,
f Y'o gbe O s’oke l' apa Re,
Iwo y'o si tunu
Amin.
569
8.8.8.D
E ma gbadura li aisimi. I Tes. 5:17

1. mf Jesu Oluwa gbgogbo wa,


T'o wa bakanna titi lae
F' eti si gbe om ' eyin Re,
Si ko wa b' a ti ngb' adura ,
Fun wa li ebun adura,
Ji wa dide k'a w' oju Re.

2. di A o le ro ero rere kan,


Ao le ni ife rere kan
Afi bi wo t' O da aye
Mi agbara ns'okan wa;
mf Gba na l'ao k' edun l' emi Re
L'ao fun O li ohun Tire.

3. di Jesu f' eti si aroye


Omo-eyin Re t' a ndanwo
mf Fun wa l' ohun ni t' a ndanwo
Ran Olututnu sokale;
Fi Emi adura fun wa,
Fi ajele Re s' okan wa.

4. mp Fi Alagbawi na fun wa,


K'o si fun wa le dinku,
Ki aniyan elese le tan
K'a le f' okun fun ebe wa
K okan wa d' ile adura.

5. mp Sokale l' emi adura


S' odo awa ti nwo' ona Re;
Ebun agbara adura,
Nikan l'a ntoro lowo Re;
Wo ki o du wa iyoku.
Amin.
570
C.M
Emi ki yio jeki O lo, bikosepe o ba sure fun mi .Gen 32:26

1. mp Olus' agutan, toju wa


Li ojo ibi yi,
Fun gbogbo omo-eyin Re
N' ipa lati sona.

2. mp B' igba idanwo wa ba pe


T' iponju po fun wa,
Jek' emi wa simi le O
L'adura aisimi.

3. mp F' ore- ofe emi ebe


Fun wa nipa gbagbo
K'a du titi ao r' oju Re,
T' ao si mo oko Re,

4. mp Titi O fun wa l' ara Re


Ati ife pipe,
K' eyi je igbe gbogbo wa
Nki o je ki O lo.

5. mf O ki O lo bikosepe
O s'oko re fun mi;
K'o f' igbala Re bukun mi
Si je ndabi Re.

6. mp Je ki nroju Re kedere
Gba m' ba ori oke;
cr Nibiti a r' ohun t'agbagbo,
f T'a dura di iyin.
Amin.
571
10.10.
O ye ki enia gbadura nigbagbogbo lai simi ati lai sare. Lk. 18:1

1. mf Ma gbadura; Emi mbebe, n' nu re,


Fun gbogbo aini re igba gbogbo.

2. mp Ma gbadura; l' abe eru ese,


Adura nri eje Jesu ti nsan.

3. Ma gbadura; b'are tile mu O,


Adura ngbe wa s' ebu te Baba,

4. f Ma gbadura; n'nu wahala aye,


cr Adural' o nfun okan n' isimi,

5. f Ma gbadura; b' ayo ba yi o ka,


cr Adura nlu harp o korin angel'

6. p Ma gbadura b' awon t'o feran ku,


cr Adura mba won mu omi iye.

7. di Gbogb' ohun ayey'o b' aye koja,


mp Adura wa titi; ma gbadura.
Amin.
572
L.M
Nibe lemi o pade re, emi o si ba o soro lati oke ite anu wa. Eks.25:22

1. mf Ninu gbogbo iji ti nja,


ninu gbogbo igbi ponju,
Abo kan mbe, ti o daju
p O wa l' abe ite anu.

2. mf Ibi kan wa ti Jesu bda


Ororo ayo s' ori wa;
O dun ju ibi gbogbo lo,
p Ite anu t' a f' eje won.

3. f IIbi kan wa fun idapo;


Nibi ore npade ore;
L' airi ra nipa igbagbo,
p Nwon y' ite anu kanna ka,

4. f A! nibo ni a ba sa si
Nigba danwo at' iponju?
A ba se le bori esu
p Bo sepe ko si te anu.

5. f A! bi idi l' a fo sibe


B'enipe aye ko si mo,
Orun wa pade okan wa,
p Ogo si bo ite anu.
Amin.
573
7.6.7.6.D
'E ma gbadura laisimi. ITes. 5:17.

1. mf Lo l'oro kutukutu,
Lo, ni osan gangan
Lo, ni igba asale,
Lo, Iogbonjo oru
Lo; t'iwo t' inu rere
Gbagbe ohun aye
p Si kunle n' iyewu re,
Gbadura,ni koko.

2. mf Ranti awon t'o fe O


At' awon t' iwo fe
Awon t'o korira re.
Si gbadura fun won;
Lehinna, toro' bukun,
Fun wo tikare,
Ninu, adura re ma
Pe oruko Jesu.

3. B' aye lati gbadura


Ni koko ko ba si;
T'okan re fe gbadura
Gbat' ore yi o ka,
Gbana, adura jeje,
Lati okan re Olorun
Alanu, Olufe,

4. f Ko si ayo kan l' aye


T'o si eyi lo
Nit' agbara t' a fun wa
Lati ma gbadura;
p Gbat' inu re k' o ba dun
Wole, k'o gbadura,
cr Ninu ayo re gbogbo
Ranti or' ofe Re`
. Amin
574
C.M
Oju Oluwa mbe lara awon olododo,
eti Re si si igbe won, OD 34:15

1. mf Oju kan mbe ti ki togbe


Nigbat' ile ba su,
Eti kan mbe ti k' ise
Gbati orun ba wo.

2. Apa kan mbe ti ko le re


Gba ' pa eniyan pin;
Ife kan mbe ti ko le ku

3. Oju na nwo awon Seraf!


Apa na d' orun mu;
Eti na kun f' orin angel'
Ife na ga l'oke
.
4. mf Ipa kan l' eniyan le lo,
Gbat' ipa gbogbo pin,
Ati ofe nla na

5. cr Ipa na ni adura wa
Ti nlo waju ite
T'o nmi owo t'o s' aye ro
Lati mu 'gbala wa.
Amin.
575
L.M
E ma duro sinsin ninu Adura igba pelu idupe. Kol 4:2

1. mf Ikose ti po to, t' a nri,


Li ona wa s' ite anu?
Sibe, tani mo yi adura
Ti ki y'o fe ma wa nibe?

2. mf Adura ni tu ojo ka,


On gun ategun Jakobu;
Adua l' agbara igbagbo,
Ni mu ibukun sokale.

3. mf Adura mu ki ija tan,


On ni se hamora kristian
Satani gbon, nigbat' ori
Elese lori ekun re.

4. mp Busi gbagbo at' ife wa


K'a le m' ore Re, Oluwa,
K'a jere eso adura,
Lat' inu isura Re wa.

5. mf B' oje daji edun okan wa


L'ongoke gege bi ebe
Orin ayo wa yoo je
W' ohun t' Oluwa se fun mi
Amin
576
8.8.8.4
Wakatiadura. Ise.A.3:1

1. mf Olorun lat' ooro d' ale,


Wakati wo l'odun pupo,
B' eyi t'o pe mi wa 'do Re,
Fun adura?

2. Ibukun n'itura oro


Ibukun si l' oju ale;
Iri bukun t' aye!

3. Gba na mole kan mo si mi


O dan ju 'mole orun lo
T' odo Re wa.

4. Gbaba l'gbara mi'd'orun,


Gbana l'o f'ireti Orun
M'ara mi ya.

5. Enu ko le so ibukun
Ti mo nri f' aini mi gbogbo
Agbara, itunu,ai
Alafia,

6. Eru at' iyemeji tan,


Okan mi f' orun se ile
p Omije ronupiwada
L'a nu kuro.

7. Titi un o de le bukun na,


Ko s'anfani t'o le dun bi
Ki nma tu okan mi fun O
Amin.
577
D.L.M
Wakati adura Ise.A3:1

1. f W akati adura didun !


T'o gbe mi lo kuro l' aye,
Lo 'waju ite Baba mi,
Ki nso gbogbo edun mi fun;
cr Nigba banuje at' aro
Adun l'abo fun okan mi;
Emi si bo lowo wsu;
Gbati mo ba gb'adua didun.

2. f Wakati adura didun,


Iye Rey'o gbe ebe mi
Lo sod' Eni T'o O se' leri
Lati bukun Okan adura,
B'o ti ko mi ki nwo 'oju Re,
Ki ngbekekle, ki nsi gba gbo;
Un o ko gbogb' aniyan mi le
Ni akoko adua didun.

3. Wakati adura didun,


Je ki nma r'itunu Re gba
Ti un o fi d' oke Pisga
Ti un o r'ile mi l' Okere;
Un o bo ago ara sile;
f Un o korin bi adua didun.
Amin.
578
S.M
.Igboiya lati wo inu ibi Mimo nipase eje Jesu Heb. 10:19

1. mf Sa wo ite-anu,
Oro Re pe f' oju rehan
Lati gbo adura

2. p Eje rtutu ni
Ti a ti ta sole
Pese ebe t'o fe,
F'awon t'o nt' Olorun.

3. p Bere ohun t'o fe,


Wo ko le bere ju;
Eni t'o eje Re sile
Kini y'o fi du O?

4. Ife le fun mi;


Ju bi mo ti fe lo;
Ama fun eni t' o bere
Ju bi won ti nfe lo.

5. Fun wa l'aworan Re
At' oju-rere Re;
Je ki nle sin O nihinyi,
Ki mba le ba O gbe,
Amin.
579
L.M
Nitori nibe ni Oluwa gbe wa pase ibukun .OD.133:3

1. f P ase' ibukun Re t' oke wa


Olorun ,s' ara Ijo yi;
mf Fi ife ti Baba wo wa
p Gbat' a f' eru gb'oju soke.

2. mf Pase ibukun Re, Jesu,


K'a le se omo eyin Re;
Soro gbogbo,
p So f' alailera, tele mi.

3. mf Pase 'bukun l'akoko yi


Emi otom kun ibi yi,
mf F'agbara iwosan Re kun,
At' ore-ofe isoji.
Amin.
580
7.7.7.7
Kini iwo nfe ti emi iba se fun O.Lk.18:41

1. mf Mura ebe, okan mi ,


Jesy nfe gb' adura re;
O ti pe k'o gbadura,
Nitorina yio gbo,

2. L'odo oban'iwo mbo,


Wa lopolop ebe;
Be l'ore-ofe Re po
Ko s' eni ti bere ju,

3. mp Mot' eru bere;


Gba mi ni eru ese;
di Ki eje t'o ta sile
We ebi okan mi nu.

4. S' odo Re, mo wa' simi,


Oluwa, gba aya mi;
Nibe, ni ki O joko
Ma nkan joba nibe,

5. B'eniyan ti nri 'ra re,


Ni inu awojiji,
Be ni k'o yo s' okan mi,
Ya aworan Re sibe.

6. N'irin ajo mi l'aye,


K'ife Re ma tu n'nu,
Bi ore at' Oluso
Mu mi d'opin irin mi.
Amin

.
581
8.7.8.7.8.7.
Ki ore-ofe Oluwa wa Jesu Kristi ki o wa pelu nyin. ITes. 5:28

1. mf Fi ibkun Re tu wa ka,
Fi ayo kun okan wa;
K' Olukuluku mo' fe Re!
K;a l'ayo n'nu ore Re;
Tu wa lara tu wa l' ara
La aginju aye ja.

2. f Ope at' iyin l'a nfun O


Fun ihinrere ayo ;
mf Je ki eso igbala Re,
Po l'okan at' iwa wa;
cr Ki oju Re, ki oju Re
Ma ba gbe titi lo.

3. p Nje n'igbat' a ba si pe wa
Lati f' aye yi sile
cr K' Angeli gbe wa lo s'orun,
L'ayo ni k'a j'a ipe na ;
f Pelu Kristi titi lae.
Amin
582
8.7.8.7D
Olorun ore-ofe gbogboti o ti pe nyin sinu
ogo Re ti ko nipekun ninu Kristi Jesu Ipet.5:10

1. f W a, iwo isun ibukun,


Mu mi korin ore Re
Odo anu ti nsan titi
Bere orin yin kikan;
Oluwa, ko mi l'orin na
T'ogun nko l' oke
Je ki nroyin isura na
Ti ife Olorun mi.

2. mf Nihin l' a ran mi lowo de


Mo gbe Ebenezer ro
cr Mo nreti nipa anu Re
Ki ndede l' alafia;
p L'alejo ni Jesu wa mi,
Gba mo sako lo l' agbo
Lati yo mi ninu egbe
O f' eje s' etutu.

3. cr Nit' or' ofe lojojumo?


Ni gbese mi si npo si
K' ore ofe yi ja ewon
Ti nse dena okan mi,
p Ki nsako sa l'okan mi nfe
Ki nko Jesu ti mo fe
cr Olugbala gba aya mi;
Mu ye f' agbara Orun
.Amin
583
10.10.10.10
Oluwa tio fi alafia bu si fun awon enia ReOD.29:11

1. f Olugbala, a tun fe f' ohun kan


Yin oruko Re k' a to tuka lo;
Ni pari sin, a dide lati yin;
p A o si kunle fun ibukun Re.

2. mp F'alafia fun wa, b' a ti nrele,


cr Je k'a pari ojo yi pelu Re;
mf Pa aya wa mo, si so ete wa
T'a fi pe oruko Re n'ile yi,

3. mp F' alafia fun wal'oru oni;


cr So ojunkun re d' imole fun wa,
Ninu ewu, yo awa omoRe,
mf Okun on ' mole j'okanna fun O.

4. mp F' alafia fun wa loj'aye wa,


cr Re wa l'ekun k'o si gbe wa nija,
mf Leyin gbogbo ijagun aye yi,
p Pe wa Baba, s' orun alafia.
Amin
584
8.7.8.7D
Ore ofe Jesu kristi Oluwa, IIkor. 13:14

1. f K' ore ofe krist' Oluwa,


Ife Baba ailopin,
Oju rere Emi mimo,
K'o t' oke ba s'ori wa;
f Bayi l' a le wa n'irepo
Awa ati Oluwa;
K'a si le ni dapo didun,
At' ayo t' aye ko ni.
Amin
585
L.M
Nigbana ni o sore ofe fun O si wipe, Gbana kuro ninu lilo sinuiho, emiti ri irapada! Jobu
33:24

1. p Bi mo ti kunle, Oluwa,
Ti mo nbe f' anu l'odo Re,
cr Wo t'ore l'ese ti nku lo,
Si tori Re gb' adura mi.

2. p Ma ro tiju at' ebi mi,


At' aimoye abawon mi,
cr Ro t'eje ti Jesu ta le
Fun dariji on iye mi.

3. mf Ranti bi mo ti je Tire,
p Ti mo je eda owo Re;
Ro b' okan mi ti fa s' ese
Bi danwo si ti yin mi ka.

4. A! ronu oro mimo Re


Ati gbogbo ileri Re
Pe, Wo O gbo adua titi
Ogo Re lati dasi,

5. p A! ma ro ti yemeji mi,
Ati ailo or- ofe Re;
Ro ti omije Jesu mi;
Si i toyeRe di t' emi.

6. mp Oju on eti Re ko se,


Agbara Re ko le lae;
Jo wo mi. okan mi wuwo,
p Da mi si, k' O ran mi lowo.
Amin
586
C.M
Ore-ofe ki o wa pelu nyin. II Tim. 4:22

1. mf F' ore-ofe Re ba wa gbe,


Jesu Olugbala
Ki eni arekereke,
K'o ma le koju wa.

2. F'' oro mimo Re wa


Olurapade wa
K'a ri igbala nihin yi
L' a ohun nihin yi.

3. F' imole ba wa gbe


Wo imole aye;
Jek' oro Re tos' amona wa
M,a si je ki a subu;

4. mf F' bukun Tire ba wa gbe,


Oluwa, Olotoro
Fi ebun orun rere Re
Bu si igbagbo wa

5. Fi pamo Tire ba wa gbe,


Iwo Alagbara;
K'a ma gbe ara le aya
K'a ma ye n'ipo wa.

6. f Fi fe fun ba wa gbe,
Oloru Olore;
Ran wa lowo ninu ponuj
Mu wa duro ti O.
Amin.
587
8.5.8.5 &Ref.
Enikeni ti o ba pe oruko Oluwa li a o gbala Joe. 2:32.
1.. f Ma koja mi, Olugbala
Gbo' adura mi,
Gbat' Iwo ba np' adura elomiran,
di Mase. Jesu, gbo, adura mi
Gbat' Iwo ba np' elomiran,
Mase k'oja mi.

2. p N'ite anu, Je k'aemi ri


Itunu didun
p T' edun t' edun ni mo wole
Jo, ran mi lowo,

3. mf N'igbekele itoju Re
L'em' o w' oju Re
p Wo' banuje okan mi san.
F' ife Re gba mi.

4. mf Wo orisun itunu mi,


Ji ye fun mi lo,
Tani mo ni l'aye lorun
Bikose Iwo
Amin
588
L.M
O ti ku fungbogbo won pe ki awon ti o walaye
ki o ma si se laye fun ara won mo 11kor.5:15

1. mf E mi ko le saini ife
Si eleda mi t'o o fe mi
Ni fifi emi Re lele
Ki emi elese le ye.

2. mp Bi nko ba fe Oluwa mi
Emiy'oje alaimore
p Iku Re y'o ha jasanbi
Lori gbogboailer mi

3. cr Oluwa jo fun mi n' ife


Ki nle ma feran Re titi
Ojo aye miy'o d'opin,
Ti un o fi wo nu ogo Re.,

4. mf Jesu, Ore toto l'O je,


Anu Re si duro laelae
Fun awon t'on se ife Re
Ni pipe n'I nu Iwa mimo

5. f Jesu t'o pa oro iku,


T'o si pa ise esu run;
T' ese ko nipa l'ori mi
Jeki ma se' l'orimi
Je ki nle ma se' fe Re lae.
Amin
589
7.7.7.7 .D
Teti sile si ebe awon enia Re ti nwon bu ba gbadura ki O si gbno li orun gbo, Ki o si
dariji IA Oba8:30
1. mp Jesu , 'Wo Od'agutan,
Ti O f' ara da' rora,
Wo t' Ose fe Baba Re
Ni fifi ese wa ji;
Awa ntoro anu Re
Ninu ebi ese wa;
Mu wa de ile ayo,
Ni 'kehin, k'a ba O gbe.

2. cr Ni'gba idamu aye,


Ma j'Oluranwlowo wa,
Yo wa ninu idanwo
Ati l' owo ota wa;
Je k'a mo riri ku Re
Lori gi agbelebu,
gbagbogbo, je k' okan wa
Ma ranti Iya t'o je.

3. mf Mu ki ife wa n'nu
Gbogbo okan ti nsako
Mu won mo adun ati
Iye ati ajinde
T'iku Re mu wa fun won,
Tobe, nikehin ki won,
Ba le je alaopin
Ijoba ayeraye.
Amin
590
10.10.10
Bi O se ti emi, o kepe Olorun, yio si gba mi. OD 55:16

1. mp Baba Orun mo na' wo mi si O;


Iranlowo miran emi ko mo;
Iwo t'o f' ewa bole bi aso
Fi Ibukun Tirewo mi l'ewu.

2. Olori Ijo orun on aye,


Fi Emi mimo Tire tun mi da;
Lo ero, okan ati emi mi
K'emi le sise iwa saye mi

3. cr Olorun Eleda gbogbo aye,


Jeki nwa O, ki nri O,ki nfe O,
Ki nfe, ki nhuwa fe si gbogb' eniyan
Kinsi f' iwa jo O nise anu.

4. mf Isun ibukun, Ife at' ayo,


Bi orun n'ijoba Re mu mi ran;
Ati lati aye yi lo k'emi
L'ayo at' ibukun orun rere
Amin.
591
C.M
Emi o gbe oju mi si ori oke wonni nibiti Iranwo mi ti n wa. OD.121:1

1. mp Ran wa lowo, Oluwa wa,


Li akoko anini;
L'ero l'oro ati n' ise,
Li ojo wa gbogbo.

2. p Nigbati Irobinuje
Mu k' okan wa gbogbe,
T'okan wa si tutu si O
Jowo, ran wa lowo.

3. mf Mu kiigbagbo wa po si,
Nipa adura wa;
B'igbagbo wa ba ti po to,
Jowo, ran wa lowo.

4. B'a wa'do Re bi alejo,


T'a wole,t'a ntoro,
Erun ori tabili Re,
Iba eyini to.

5. mf Sugbon, Oluwa alanu,


O ki o s'aifun wa;
Erun ori tabili Re
j'ayo, mole iye.

6. cr Ran wa lowo lat' oke wa,


Ao ni ranwo miran;
Ran wa lowo k' a je Tire
L'aye ati l'orun.
Amin
592
7.7.7.7D
Oluwa, emi ko gbe okan mi ga, beni oju mi ko gbe soke OD.131:1.

1. mp Jesu, nigbat' a wole,


Ni' teriba, lese Re;
A fere ma le w'oke
F'ekun 'ronupiwada,
p A wo gbogbo 'rora Re
T'o je laye n'tori wa,
Siju anu Re wo wa,
Gbo adura ebe wa,

2. cr Ranti igba ewe Re,


Igba anini at' ekun
Li aginju aye yi,
mp Ranti'gba ti Esu nfe
F'arekereke mu O,
F' oju adura ebe wa.

3. pp Wo ekun Re kikoro
Lori oku Lazarus;
W o omije Re t' o san,
Lori Jersalemu,
p Wo edun t'o fi so pe;
Odale mbe t'o lagbo Re;
Lati' bugbe Re Orun
Gbo adura ebe wa.

4. p Ranti 'gba t'eru ba O


Ati' waya-ija Re,
Ranti ewu esin ni,
Ogbe at' ade egun;
Ranti okunkun t' o su,
Gbat' O f'ara Re rubo,
Gbo adura ebe wa.

5. p Ranti oro ikehin,


At' edidi t' a fi se
Iboji t'okunkun Re
Ko le se Oluwa mo,
mp Olorun alagbara,
Ti o goke lo's orun,
Jo festisi igbe wa,
Sigb' adura ebe wa!
Amin
593
S.M
Wo Odagutan Olorun. Jn.1:36

1. mp Iwo Od-agutan.
T'o ta je Fun wa,
T'o mu wa jade ni Egypt;
To awon eni Re.

2. cr Angel' ore- ofe


Jowo agbara Re;
Wa be, awon ayanfe Re,
Ni ibudo Israel'.

3. mf F' imole Re to wa,


Ja ona aginju;
Je awo-sanma li osan
Ati ina l' oru.

4. mf Fi ibukun Orun
Gb' emi ara wa ro;
Si rojo manna ife Re
Sori awon Tire.
Amin.
594
8.8.6 .D
E ji iji odoodo, ki e ma si dese. Ikor. 15:34

1. cr Olorun awaamaridi
T' fe nsin mi bo pele
Lat' igba ewe mi ,
Jo, jwki nri nu okan mi
Ki nmo bi m' ba ni dalare
Nipa or'-ofe Re.

2. di B'o ba se pe mo m' eru Re


Ti mo si f' okan oto je
Ipe atokewa,
Busi or-ofe t'o fun mi,
Si jeki okan mi mo adun
Ifiji ife Re

3. Nki o wa laini ife Re


Laini rti n' nu oro Re
Laini imo fiji;
Baba, nki o tan 'ra mi je,
Ki ns' alaini Eleri na
Ti s' apere Orun.

4. cr B' Eleri na ba ngbe n'nu mi


Ki o ha so t' ilaja Re
T'a se nipsa Jesu?
Un ofi igbagbo sunmo O
Un o f' igboya ke pe Baba.
Un o mo ra mi n' Tire.

5. mp Ohun kohun t'o le dena,


Idariji fe Re si mi ,
Ki ogo Re le tan;
Jeki okan mi gba o gbo,
F' gbogbo ese mi ji mi,
Si ko gbogbo won lo.

6. mf Baba, f' omo Re han n' nu mi


Si jeki okan mi le mo
B'anu Re ti po to;
F' asiri ife Re han mi,
Ma gbe nu okan mi titi
Nipa Emi mimo.
Amin.
595
S.M
Oluwa , fi eti si ebe mi.OD. 143:1

1. mf Jesu, gb' adura mi,


Fetisi igbe mi;
Jo ranti oro oto Re,
Si f' or'ofe dahn.

2. cr Mase se idajo
Emi iranse Re;
N'tori ko si alaye kan
T' o pe lo oju Re

3. mp Mo tewao mi soke
Siha ' bi mimo Re;
Okan mi apongbe , b' asale,
Faun 'tura ore Re.

4. di Oluwa, jo yara,
Gb' okan are mi lat!
Ma m' oju kuro lara mi;
Emi dabi oku.

5. cr Igbagbo mi nfe ri
Imole anu Re;
Jo jeki nrin niwaju Re
Mo gb' okan mi si O

6. mp Jek' Emi Re to mi
Si ona ododo;
Oluwa, n'toro oko Re
Gbe mi leke ibi.
Amin
596
7.7..7.D
Oluwa ni ipin mi nitorina ni mi se ni ireti ni nu Re. E. Jer.3:24

1. f Jesu, Olus'agutan,
Sanu aibal' okan mi
Ma to mi , si pa mi mo,
Ti ife Re se mi pe;
So di yiye koro,
Jeki igbagbo mi daju.

2 mp Nko le duro pe titi


Nigbagbo ni mo nsipo;
cr Sugbon O wa bakanna,
L'ana, l' oni, titi lae;
f Fun mi n' iduro- sinsin,
F'or' ofe m' okan mi le

3. f Jek' ibagbo gbe mi ro gbe mi ro,


Larin wahala aye;
Jeki ireti mimo
Se' dakoro okam mi
Se mi pe mimo
Se dakoro okan mi
Ki nle je Tire titi
Amin
597
10.11.11.11.
Ninu ohun gbogbo ki O le ipo ti o ga julo. Ko l:18

1. f Je irran okan mi ,Oluwa


Si je rere gbogbofun mi kriti;
mf Losan , loru, mi oro ototo
Ki o si jew molemi nigbagbogbo

2. f Je oye mi, oro otito mi;


Wa pelu mi, lai at' emi pelu Re;
mf Je Baba fun mi, k' emi je omo Re
Ma gbe nu mi', k a si Je okansoso.

3. f Je abo ida fun ija na


Je ihamora ati agbara mi;
mf Je ihmora ati agbara,gbo okan mi,
To mi s' on orun, Alagbara julo

4. f Nko lepa oro tabi yin eda,


Je ipin mi nisiyi ati laelae;
mf Wa, ko si je ekhin n'isura mi.

5. f Oba giga orun, mole


Jo fun ba n'nu lehun isegun mi.
f Okan giga orun . mi, Alase
eda. Amin.
598
8.7.5.77..6.6.8.7
Fa mi, awa o sare to O. O.sol.1:4

1. mf Jesu Wo ni t' emi laelae


O ju gbogbo ore lo;
cr Nigbogbo irin-ajo mi
A1 mba le faramo O,
mp Sunmo O, sunmo O,
Sunmo O, Sunmo O,
cr Ni gbogbo irin-ajo mi O,
A! mba le faramo O,

2 mf K' ise fun oro aye yi


Ni mo se ngbadura yi;
cr Tayotayo ni un o jiya
Bi mba sa le sunmo O,
mp Sunmo O, Sunmo O,
Sunmo O, Sunmo O,
cr Tayotayo ni un o jiya
Bi mba sa le sunmo O,

3. mf Gbat' ajo mi ba si dopin


Mu mi gunle sodo Re,
cr Si ilekun ayeraye
Ki nsunmo O, titi lae
mp Sunmo O, sunmo O,
Sunmo O, sunmo O,
cr Si ilekun ayeraye
kI nsunmo O titi lae.
Amin.
599
8.7.8.7.D
ki Olorun ki o sanu fun wa ki o si busi fun wa O.D 67:1

1. f Baba wa , Eleda orun,


Gbo ti wa l' akoko yi.
Fi ore -ofe Re kun wa
K'a le j omo eyin Re.
mf Bukun wa , Baba, a mbe O,
Dahun ebe wa loni,
Mase je k' awa lo lo fo,
F' ire kari wa, Baba.

2. cr Awon t' o wa O n'gb ' aye Re


Enikan, ko le lofo;
B' anini gbogbo won Baba.
L'o si bukun fun won to,

3. cr Ikunle wa j'okan soso


Sgbon ebe wa yato;
Alailera n fe iwosan,
Alaini ntoro' bukun.

4. f Fi' dahun' bere wa fun wa


B' a ti nw'oju Re loni;
Ki gbogbo wa f'ayo wipe,
A ti ri idahun gba'
Amin
600
7.7.7.7
Emi kigbe pe O, Oluwa, OD 30:8

1. mf Wa, Jesu fi ara han,


Wa, je k' okan wa mo O;
Wa, mu gbogb' okan gbona,
Wa, bukun wa k'a o lo.

2. Wa, f'aya wa n' isimi,


Wa, k' a alabukun fun;
Wa, soro alafia,
Wa, busi igbagbo wa.

3. f Wa, le siyemeji lo,


Wa , ko wa b'a ti bebe;
Wa , fun okan wa n'ife,
Wa, fa okan wa soke.

4. f Wa, so f' okan wa k'o yo,


Wa, wipe Wo ni mo yan;
Wa, p awon agbo Re mo,
Wa, sure f'agutan Re
Amin.
601
C.M
E jeki a fi igboiya wa si ibi ite ore-ofe ki a le ri anu gba. Heb. 4:16

1. mp I te anu e je k' a lo
Lati gba adura;
Olrun fe y'o sanu fun
Awon t'o nsin nibe.

2. mp Ite anu a n'ite na


L'ekun wa ti nkunle;
Olorun si nro jo bukun
Nigbakugba t' a lo.

3. mf Te anu eyin mimo ye


Ite na sile;
Fi edun yin han Olorun,
Si wa di ife Re,

4. A ko le sai fe anu,
Niwon bi a ti wa,
p Ati onigbowo, titi
Iku y'o pa wa da,

5. mf Gbana oju Jesu yoo tan


Mole y'ite na ka,
A ki si mo aini mo,
Ak'y'o wa te anu.
Amin
602
11.10.11.10.
Nitori awa gbekele Olorun alaye ITim 4:10.

1. mf L' odo Re sibe nigbat' ojumo mo,


Ti awon eye ji ti kuku lo;
Rekoja t'' orun ni didan imole,
Idaloju pe, O wa lodo mi.

2. p Nigbati are mu okan mi togbe,


O ko ju si O ninu adura;
Orun na, ti dun to labe iji Re,
Sugbon k'a ji k'a ri O dun Julo.

3. mf Beni, yoo ri l'owuro ikeyin ni,


Ti okan ji , ti kuku aye lo;
Gbana ninu ewa t'o ta re yoo soji.
Amin.
603
C.M
Iwo ni ki ose ibujoko apata mi. OD 71:3

1. Oluwa , Wo ki o si gba,
Eni osi b'emi ,
K'emi le sunmo ite Re,
Ki nke Aba, Baba?

2. Jesu , Jowo fi oro Re


S'okunkun mi d'osan;
Ki gbogbo ayo tun pada,
Ti mo f'ese gbon nu.

3. Oluwa mo f' iyanu sin,


Ore Re tobi ju;
Pa mi ninu ife Re,
K'emi ma d' ese mo.
Amin
604
C.M
Omo mi, fi okan mi gege re fun mi.Owe 23:26

1. mf Gb'okan mi gege b' o ti ri,


Te ite Re sibe;
Ki nle fe O ju aye lo,
Ki nwa fun O nikan..

2. Pari;se Re Oluwa mi,


Mu mi je oloto;
K' emi le gbohun Re, Jesu,
Ti o kun fun ife .

3. Ohun ti nko mi n'ife Re,


Ti nso 'hun ti mba se;
Ti ndoju ti mi , nigba nko
Ba topa ona Re.

4. Em' iba ma ni eko yi,


T'o nti odo eko wa,
Ki nko' teriba s' ohun Re,
At' oro isoye.
Amin
605
L.M
Oluwa kiyesi aroye mi. OD. 5:1.

1. f Oluwa, gbo aroye mi,


Gbo adura ikoko mi,
Lodo Re nikan , Oba mi;
L'emi o ma irawo .

2. mf L'oro Iwo o gbohun mi;


L'afemojumo ojo na;
Ni odo Re l'emi o Wo,
Si O l'emi o gbadura.

3. Sugbon nogb' ore -ofe Re


Ba mu mi de agbala Re,
Odo Re l'emi o teju mo,
Nibe un o sin O n' irele.

4. f Je k'awon t' o gbekele O,


ff L' ohun rara wi ayo won;
Je k'awon t' Iwo pamo Yo,
Awon t' o fe oruko Re.

5. f Si olododo l' Oluwa


O na owo ibukun Re;
Ojurere Re l' eniyan Re
yio si fi asa won.
Amin
606
6.4.6.4.6.6.4.
Oluwa si nlo niwaju won . Eks 13:21

1. mp Fun mi bn' iwa pele


Okan tutu;
Ifarabale bi
T' Oluwa mi;
p Irele on suru
At' opo iyonu,
cr Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

2. mp Fun mi n'itelorun
N' ipo k' ipo;
Ko le re 'le ju yi
T'a bi Jesu./
cr Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

3. mp Fun mi ni itara
S' ipa Tire;
Aniyan at' ife;
S'ohun t' orun;
p Fun mi n' iwa mimo,
Ikorira ese.
cr Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

4. mp Fun mi ni igbagbo
At' ireti;
Fun mi ;'ayo 'agbala
Ninu Jesu;
f F'emi iye fun mi,
Fun mi l'ade ogo;
ff Gbati mo ba Jinde
Ki njo Jesu.
Amin.
607
6.6.6.6.8.8
Emi o ma korin iyin si Olorun mi .OD 104: 33

1. Si ohun ti a gbin
Se iri 'bukun Re;
Agbara ni k'o Tire;
Lati mu k'o dagba;
Iyin a je Tire nikan
.Amin
608
7s
Eniyan o si saferi mi e o wa mi Jer. 29:13

1. mf Oluwa, a wa do' Re
L'ese l' a kunle si;
A ma kegan ebe wa,
A! ma a wa O lasan bi?

2. L' ona ti O yan fun wa


L 'a nwo O lowolowo ;
Oluwa, a ki o lo,
Titi ' Wo o bukun wa.

3 Ranse lat' oro Re wa


Ti o fi ayo fun wa
Je ki Emi Re k'o fun
Okan wa ni igbala.

4. Je ki a wa ,K'a si ri O,
Ni Olorun Olore ;
Ki gbogbo wa yo gbekun si
W' alaisan da gbekun si
Ki agbogbo wa yo si O
Amin
609
S.M
O ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun Rom 13:11

1. Ol urapada mi,
Gb' emi n'n' orun yi
So fun mi nisiyi ji! ji!
Kristi yo wo o San.

2. f Gbe owo Re le mi;


Ji mi nisiyi,
Je ki oye ye tmi daju
B' agbara Re ti to .

3. mp Je ki nle ke pe O
K' emi si ma sora
Ki nma ba bo sinu danwo,
K;asa mi ma sonu.

4. Je ki nmura sile mi;


De ikolu n' iduro gangan lae,
K' emi si ma wo O

5. di Wo ri ailera mi;
cr Krist ' je agbara mi,
mf Ranlowo mi ninu ponju
Abo at' odi mi .

6 Je ki ngb' okan le O,
cr Je ibugbe fun mi,
f Iwo apata, asa mi,
At' Olugbala mi.

7. p Nko legba ' ra mi la,


Nko le pa 'ra mi mo;
cr Agbara mi t' owo Re wa,
mf Wo eni ti ki sun.

8. mf Iwo.nikansoso
Ni mo f' emi fun;
cr Jesu, fe mi b' awon Tire;
f Si fe mi de opin
.Amin.
610
13.13 .12.12.&.Ref.
Nitori Emi ni Oluwa ti o mu O larada.Eks.15:26

1. f Gbo iro ese Jesu ,O nkoja lo bayi ,


O ni tura f' agbogbe, O ns' awotan arun;
Bo ti so alaisan ni, leti adagun,
O nwi be nisisiyi, OI nfe 'wosan bi?
mf O nfe'wosan bi?
O nfe'wosan bi?
p Wa, alailera wa;
Wa, elese wa;
f Wo omi iye ti nsan,
Wo inu re, iwo yo si 'wosan.

2. f Ohun Olugbala ni, ipe anu Re,


Mu igbala ofe wa fun gbogbo eniyan;
O npe gbogbo okan ti eru ese npa,
O nfi ife bere pe O nfe wosan bi?

3. mf Ara nni O, eru nwo O l'orun,


O ko ha le wonu omi ni bi o ti nru;
f O si nfi bere pe, O nfe wosan bi?

4. mp Ran wa lowo Jesu ka gbeke l' oro Re,


Je ki emi iwosan ba le wa loni yi,
We abawon ese nu , si s' akoso wa,
So f' okan to nwa o pe , O nfe 'wo
Amin
611
L.M
Won si to wa iha gbogbo wa. Mk. 1:45

1. p Jesu, Wo Onisegun nla


T'olokunrun nf'ailera mo,
Nigba aisan at' irora,
O se dida ara fun won.

2. p Afoju, aro, alaisan,


Won ko sai ri toju Re gba,
Torina, awa s' odo Re,
A ntoro anu Re nikan.

3. p Irora ti Wo la koja,
Jesu, Wo le se wosan re
Awon to nw' onisegun nla
Jo masai se iwosan Won.

4. p Oluwa, je ki irora
M'alaisan tubo sun mo O;
Ki owo egba Re kokan
Fa asako sunm' odo Re.

5. cr Se wosan okan to gb' ogbe


Si gba okan ese wa la;
Fopo ilra Refun wa
Amin.
612
7.7.7.7.
Nigbati O ri eniyan ,anu won se E. Mat.9:36

1. mf Gbati Jesu wa l'aye,


O nsore, O si nsanu;
f Ko s' eni t'o kere ju
Ti ko sai anu han fun.

2. mf Awon afoju nyika


Ayaro at'aditi;
f Gbogbo won li gbogbo won.
O si nbukun gbogbo won.

3. mf O le wo adete san
O f'onje bo egberun;
Iji okun ngbo Tire
Oro Re ji oku n'de.

4. mf Awon elese yi ka;


Won nyo lati gb' oro Re
Awon ota Re papa
L'oro Re ya lenu ju.

5. mf F' ife Re han mi , Jesu ,


F' ore-ofe Re kun mi;
F' owo iwosan to mi
Sure fun mi, bukun mi.
Amin.
613
10.6.1..6.&.Ref.
Nitori O wi ninu re ara re pe, bi mo ba sa le fi owo kan aso Re ara mi o da .Mat.9:21

1. I seti Re lo f' owokan


Bo ti sunmo 'do Re;
mf Larin opo eniyan to pejo
O si r'iwosan gba .
f Dide, fowokan aso Re;
Iwo yo r' iwosan Re sibe
Yo mu O lara le.

2. p Teruteru l' obinrin na wole,


Olugbala ti de;
mf Ase iwosan jade lara Re
O si mu larada.

3. cr Jesu yipada, O soro ; tunu;


f Ma lo pelu gbagbo;
Alafia de sin ' obinrin na,
Ayo kun okan re.
Amin.
614
D.C.M
Nse dida ara gbogbo awon ti esu si npon loju. Ise A .10:38

1. mf Apa Re li ojo wonni


Nwosan, o si ngbala;
O nsegun iku at' aisan ,
Ati isa oku;
cr Awon afoju nto O wa,
Aro at' amukun;
Adete, alarun;
Gbogbo won r' iwosan.

2. mf Ase iwosan ntu jade


Ti nmu won larada;
Omode at' agbalagba,
Won nri idasile;
cr Sunmo wa lati bukun wa
Bi ti ojo 'gbani;
Egberun nfowokan O,
Won nfo soke f' ayo.

3 mf Iwo je Onisegun wa
Jesu Oba iye;
Tun wa soji si bukun wa,
Nip' agbara nla Re;
cr Fi ogbon orun Re kun wa,
So ope d' ologbon;
Ki gbogbo wa gbohun s'oke
Lati yin O titi.
Amin.
615
8.7.8.7.D
Jesu kristi okan na ni li ana ati li oni titi lae. Heb.13:8

1. mf Jesu , okan na titi


Bi o ti nigbani;
Lasan li orun apadi
Ndojuko agbara Re,
L'okan awon eniyan Re,
O njoba titi d'oni;
f Tire ni gbogbo agbara,
O nfa ide ese ja.

2. mf Jesu ,okan na titi,


O nwosan titi d' oni,
Ko s'alaisan to le pada
Lai fun n' imularda;
O nwo aisan to buruju,
O sa mo ailera wa,
f O le ru 'banuje wa lo
Bi a ba ko won to wa,

3. mf Jesu , okan na titi,


Ka sa ma gbe inu Re;
Ko sa soohun ti o le ya wa
Ninu ife Oluwa;
O le ko aniyan wa lo
O si le tu wa ninu;
f Olugbala to sowon ju,
Ko s' oruko bi Tire
Amin.
616
C.M
Jesu Kristiokan na li ana ati li oni, ati titi lae. Heb 13:8

1. cr Jesu, p'ase iwosan Re


Mbe bakanna d' oni,
Jeki agbara oruko Re
Wo ailera mi san.

2. cr B' Iwo ba nse ore sibe


Fun awon alaini.
Se ise' yanu Re fun mi
Ki nle f' yin Re han.

3. cr Jesu, mo kepe O loni,


Tun s'ise' yanu Re;
F' anu wo emi adete,
Mo wole lese Re.

4. mp Eti mi di si ofin Re
Jesu, si mi l'eti,
Pae k' owo mi riro na
Ki ngbe soke si O.

5. cr Bi aro di si ofin Re
Jesu , nri okun gba;
Un o fo soke bi agborin,
Un o fo tayo-tayo.

6. Mo j' afoju lat' inu wa,


Okan mi sokunkun ;
Nko le ri ife Olorun
Nko mo riri ese.

7. mf Mo gbo pe Iwo nkoja lo,


Jo mas' aisunmoi mi.
f Jesu, Iwo omo Dafidi;
Sanu, gbo ebe mi ,

8. Wo, mo duro de O lona,


Iwo mole Orun;
Pase ka fa mi wa , so pe,
Elese la 'ju re.
Amin
617
L.M
Emi ko wa ipe awon olododo, bikose awon elese si ironupiwada. Lk 5:32

1. mf W o t'opo enyan wa woto,


Lati gboro iyanu Re
cr Jek' elese sunmo 'do Re,
Si f' oju re tewogba wa.

2. mf Wo so p' eni t'ara re le


Ko wa onisegun rara;
Emi ko san , mo nfe wosan,
Mo nfe agbara gbala Re.

3. Agbara, oto ife Re.


Bakanna ni titi aye;
Gholohun kan lat' nu Re
Le w' arun to buru ju san.

4. mp Bi mo ti s' ainirawo to ,
Ti si pe let' addagun,
Gholohun kan yo gbe mi n' de.
Yo wo mi san lesekanna.

5. Egberun tab' egba odun,


Bakanna ni nwon loju Re;
Logan, t' or-ofe ba de
Arun uyo san , emi o bo.

6. f Wa, Onisegun okan mi;


S'akoko yi n'itewogba;
F' ipa iwenumo Re han,
F' igbala Re han nisiyi.
Amin.
618
L.M
Emi fi ohun kigbe si Olorun o si fi eti si mi OD 77:1

1. mf Olorun mi, wo l'em' o pe,


p Ara nni mi , gbo igbe mi;
cr Gba san omi ba bori mi,
Ma je k' okan mi fasehin.

2. Iwo ore alailera,


Tani mba saroye mi fun ?
Bikose wo nokansoso,
T'o npe k' otosi w'odo Re?

3. p Tal' o sokun to lasan ri?


Wo ko igbe enikan ri?
Se iwo ni o ti so pe,
Enikan k' yo wa o lasan?

4. p Eyi' ba je binuje mi
Pe ,o ko ndahun adura;
Sugbon wo mbegbe fun mi;
Eni ti Jesu mbebe fun,
O bo lowo gbogbo 'yonu.
Amin
619
7.7.7.7
Oluwa, mase ba mi wi ni ibinu Re OD 6:1

1. mf Olorun , fi opa Re
p Ba mi li ori jeje,
Daw' binu labe duro,
Ki nma subu labe re.

2. p Wo ailrea mi yi san,
Wo mi, mo nwa ore Re;
Eyi nikan l' ebe mi,
Wo mi, nipa anu Re.

3. Tabl' o wa n' isa -oku,


T' o le so ti gbala Re?
Oluwa, d' okan mi ro
f Fohun, emi o si ye.

4. Wo o de o gb' ebe mi ,
O de ojiji koja;
Ogo si tun yi mi ka ,
Okanmi ,dide k' o yin.
Amin.
620
7.7.7.7
Emi ki yio fi nyin sile.Jn.14:18

1. Jesu awa nwo O fun


Wosan alaiera yi
Wo lo ti se anu nla,
F' abirun let' adagun.

2. Ko s' onisegun bi Re;


Ti w' ara okan san,
Wo lo ji omobinrin
Jairu dide nin' oku.

3. Lasaru ti s' aisan ri,


O ku, a sin i n boji,
Sugbon wo' nisegun nla,
J'oku jo kerin dide.

4. p Jesu jo dari ji wa,


Ba wa wo alaisan yi,
cr K'o le dide f' ogo Re,
f Ki a le f' ope fun O.

5. f Wo ko w' aisan kan ti ri,


Ninu igbe aye Re,
O ti wi nin ' anu Re,
Pe leri Re ko ni ye.
Amin.
621
S.M
Emi o gbekele, emi ki yio si beru. Isa 12: 2

1. p Mogbekele mi le O,
Lori ibusun mi,
Gba mi lowo irora mi,
Ki o si mi san.

2. p Kos' elomiran mo.


Ti mo tun gbekele,
O san fun ya aya pita
Ninu ailera re.

3. Obinrin igbani
Pelu isun eje,
Nipa iseti aso Re
O ri mularada.

4. p Wo mi san Oluwa,
Ninu ailera mi,
Emi ko gbodo ber' aisan,.
Emi mo gbekele O.
Amin
622
S.M
Alaye, alaye, on ni yio yin O, Isa 38:19

1. cr Ise Oluwa,
Awamaridi ni,
Ohun gbogbo ni mu 're wa,
F' eni to se 'fe Re.

2. p O ri ailera mi.
Aisan at' aigbadun
Irora mi losan loru,
Orun ko si l'oju.

3. p Wo wahala mi yi,
Wo Onisegun nla,
Si fun mi bi t' Hesikaya
'Mo gbo adura re.

4. W' awon to nsike mi,


Ati Onisegun,
Wi fun mi bi t' Hesikaya,
pp Mo ti r' omije re.

5. p Ma wo ailera mi
Dari ese ji mi,
Wo mi san bi t' Hesikaya,
Si bukun ojo mi.

6. f Mu mi wulo fun O,
Lehin ilera mi ,
B' ise mi l'aye si d' opin,
Mu mi wo 'nu ogo.
Amin
623
7.7.7.7
Tujuka, a dari ese re ji O. Mat. 9: 2

1. mf Jesu , nigba aye Re,


O ko dekun wo arun;
Igbe irora aisan
Ko kan O k'o boi le ri,

2. mf Oju anu Re ko gba


K' elese ma je rora,
di B'o tile je pe 'ya na
To si fun ese re.

3. mp Ninu ija ki emi


Le bo l'owo iparun,
O ko gbagbe p' alafia
T'o s' eran ara pelu.

4. p B' alaisan ijo wa wo


Lor akete irora,
Onisegun ododo,
Se awotan arun re.

5. F'opo itunu fun u,


K'o le gbe ara le O.
K'o mo pe Iwo nikan
L'o le pa, l' le gbala.

6. Ma je k'o siyemji,
Ki irora mu bo hun,
p Funl' ebun lati wipe'
'B iye, iku, b' ijo wa san.
Bi beko, awa mo pe
Fun rere ni ife Re.
Amin.
624
C.M
Eniti o si tan gbogbo arun re.,OD. 103:3

1. mf Eni t' o la ' ju afoju,


Ti o mu ope gbon,
At' eni t' o da imole,
Fun eni okunkun.

2. Eni t'o le fi aggbara


F'awon olokunkun,
Ti o si fi emi iye
p Fun awon t'o ti ku.

3. Eni fi dasile f' okan,


T'o gb' eni subu nde,
T'o si pa ibinuje da
S' orin pelu iyin.

4. f Wo Onisegun okan mi,


Si O l' awa nkorin,
Titi aye o fi d'opin,
Tire l' ope O se.
Amin.
625
11.12.11.&.Ref.
Awon ti nwa ki yio se alani ohun ti o dara. OD 34:10

1. mf Lionakona, 'Oluwa y'o pese'


O le s'ais' ona mi , o le sai se tire,
Sugbon l' ona ara Re li on o pese
Ao gbeke l' Oluwa on y'o si pese;
Loto , ao gbekel'E on y'o pese.

2. L' akoko t' o ye, ' Oluwa y'o pese'


O le ma se 'gba mi ko ti O so
L'akoko Tire,' Oluwa l' y'o pese,'

3. Ma beru tori 'Oluwa y'o pese'


Eyi ni ' leri Re ko s' oro ti O so
Ti si yipada; 'Oluwa y'o pese'

4. f Yan lo aibikita okun y'o pinya


Ao f' orin Isegun se ona Re l'ogo,
Ao jumo gberin ,' Oluwa y'o pese'
Amin
626
8.4.8.4.8.8.8.4.
Alafia ki o wa bi ?Alafia ni IIA Oba 4:26.

1. mf Nipa ife Olugbala,


Ki y'o si nkan;
Oju rere Re kipada
Ki y'o si nkan;
p Owon l' eje t' o wa san;
Pipe l' edidi or-ofe;
p Agbara l' owo t'o gba ni
Ko le si nkan,

2. p Bi a wa ninu iponju,
f Ki y'o si nkan;
Igbala kikun ni tiwa,
Ko le si nkan.
cr Igbekele Olorun Dun;
Gbigbe inu Kristi l'ere,
Emi si nso wa di mimo,
Ko le si nkan.

3. f Ojo , ola tio dara,


Ki y'o si nkan,
cr Gbagbo le korin n'nu ponju
Ki y'o si nkan,
mf Agbekele 'fe Baba wa;
Jesu nfun wa l' ohun gbgogbo
di Ni yiye tabi ni kiku;
f Ko le si nkan.
Amin.
627
8.8.8.D
Nitori a fi ipile re sole lori apata. Mat.7:25

1. f Igbagbo mi duro l'ori,


Eje at' ododo Jesu,
di Nko je gbekele ohun kan,
cr Leyin oruko nla Jesu.
ff Mo duro le kristi Apata,
Ile miran, Iyanrin ni.

2. f B' ire-ije mi tile gun


Or-ofe Re ko yi pada;
B'o ti wu ki iji na le to
Idakoro mi ko ni ye.

3. f Majemu, ati eje Re


L'em' o ro mo, bi kun mi de;
di Gbati ko s' atileyin mo
f On je ireti nla fun mi.

4. f Gbati ipe' keyin ba si dun,


mp A mba le wa ninu Jesu;
cr Ki nwo ododo Re nikan
Ki nduro niwaju ite,
Amin.
628
C.M
Bu si igbagbo wa. Lk. 17:5

1. mf A ba le n' igba gbo aaye,


B'o ti wu k' ota po,
Igbagbo ti ko je mi ra
Fun aini at' osi.

2 p Igbagbo ti ko je rahun
L'abe ibawi Re
cr Sugbon ti nsimi l' Olorun
Nigba ibanuje.

3. mf Igbagbo ti ntan siwaju


Gbati iji ponju de;
Ti ko si je siyemeji
N'nu wahala gbogbo.

4. mf Igbagbo ti ngb' ona toro,


p Titi emi o pin,
cr Ti y'o si f' imole orun
Tan akete iku.

5. mf Jesu f' gbagbo yi fun mi,


Nje b' o ti wu k' o ri,
cr Lat' aye yi lo , un o l'ayo
llu orun rere.
Amin
629
6.7.7.7.6 &Ref.
Nipa ore-ofe ni a ngba nyin la Efe 2:8

1. mp Ekun ko le gba mi,;


Bi mo le f' ekun we ju;
Ko mo mu eru mi tan;
Ekun ko le gba mi,
mf Jesu sun o ku fun mi,
O jiya l 'ori igi,
Lati so si mi d' omiran,
f On na l' o le gba mi.

2. mf Ise ko le gba mi,


Ise mi t' o dara ju,
Ero mi t'o mo julo,
Ko le so 'kan mi d' otun
Ise ko le gba mi.

3. mf Duro ko le gba mi,


Eni t' junu nimi,
L'eti mi l'anu nke pe,
Bi mo ba duro , un o ku;
Duro ko le gba mi.

4. f Igbagbo le gba mi,


Je ki ngbekel' Omo Re
Je ki ngbekele se Re.
Je ki nsa si apa Re,
Igbagbo le gba mi.
Amin
630
8.8.8.D
Alabukun li awon ti ko ri mi, sugbon ti nwon gbagbo. Jn 20:29

1. mp Om' Olorun, a ko ri O,
Gba t' O wa s' aye, iku yi;
Awa ko ri ibugbe Re;
Ni Nasareti ti a gan,
Sugbon a gbagbo p’ ese Re
Ti te ta Re kakiri

2. p A ko ri O lori igi,
T'eyan buburu kan O mo
A ko gbo igbe Re, wipe
'Dariji won , tor' aimo won'
f Sibe, gbagbo pe ; ku Re
Mi aye , o si orun su.

3. mf A ko duro l' eti boji


A ko a gbe te O si,
A ko joko 'nu yara ni,
A ko ri O l' oju ona
f Sugbon a gbagbo p' angeli
W ipe, Iwo ti ji dide'

4. mf A ko r' awon wonni t' o yan


Lati ri goke r'orun Re;
cr Won ko fiitanu woke
p Won si f' eru dojubole
Sugbon ,a gba oro Re gbo
Jesu , olurapada wa .
Amin.
631
C.M
Lasi ,igbabo , o soro lati wu u Heb.11:6

1. mf Igbagbo l' ategun t'o so


Orun at' aye po;
On l' Olgbala fi sise
Iyanu Re l' aye.

2. mf Igbagbo ni keke Enok'


Ti o gun lo s' Orun ;
On l' ogba ju meta ni la,
L'o gba Daniel pelu.

3. mf Lor' Igbagbo ni Noa ko


Oko igbala ni;
On l'agbara t'o gb' Elija
Wo inu sanma lo.

4. mf Igbagbo n' ipile reti,


O le se ohun nla;
Otito igbara ikeyin ti
Ohun ti ko si wa..

5. mf On l'agbara ase 'kini


T'o mu ki aye wa;
On l'agbara ikeyin ti
Yo gba elese la

6. f K'o ri fun o b' igbagbo re'


L' Olugbala wa wi;
A' je ngba ohun nla gbo
Si O, Oluwa mi.
Amin.
632
C.M
Ma da mi ro . Gen 24:56

1. mf L' ona gbogbo t' Oluwa yan,


Ajo mi lem' o to
Ma da mi ro, eyin mimo
Emi o ba yin Lo

2. Bi Jesu nlo ninu ina,


Emi o to leyin
f Ma da mi ro l'emi o ke
B'aye d' oju ko mi.

3. Ninu isin at' idanwo


Em' o lo l'ase Re,
Ma da mi ro , emi o lo,
S'ile k'igbe Imanuel'.

4. Gba Olugbala mi ba pe
Sibe k' igbe mi je
Ma da mi ro oku ma bo
Un o ba o lo l' ayo.
Amin.
633 11.11.11.11.&.Ref
E ma si se fun fi aye fun esu. Efe. 4:27

1. mp Ma f' ara fun 'danwo , nitor' ese ni,


Isegun kan yo tun fun o l'agbara;
Ja bi okunrin, si bori ' fekufe,
mf Sa tejumo Jesu , si y' o mu o laja.
pp Bere ranwo at' agbara lodo Olugbala,
mf O se tan fun iranwo, Oun y'o O mu o la ja.

2 mp Ma kegbe buburu, ma soro ibi,


Mae pe oruko Olorun l'asan;
Je eni ti nronu at' Olotito;
mf Sa tejumo Jesu, y'o mu o la ja

3. mf Olorun y'o f' ade f' eni t'o segun,


Ao fi gbagbo segun b' ota nde si wa;
Kristi y'o so agbara wa di otun,
Sa tejumo Jesu, y'o mu o la ja.
Amin
634
C.M
Ki o ri nyin , gege bi igbagbo nyin. Mat. 9:29

1. Igbagbo t' ori leri na


Ti ko soro si,
T' o nwo Olorun nikan,
T'o nwipe, Ao segun'

2. A; Eyi koja oye mi


Sugbon nki yo beru
Tor' Oluwa ti se ' leri,
Oro Re ki tase.

3. Igbagbo nla ti ki tase


Baba jo fifun mi,
Igbagbo to duro gangan
Titi y'o fi segun.
Amin.
635
7.7.7.5
Bere ao si fi fun nyin. Mat. 7.7.

1. mf Y 'o dahun gbogb' adura


Ileri ati' fe Re
Ko sa ti pada ri;
Ogo f' oko Re.

2. mf Y'o dahun gbogb' adura


Un o ro mo ileri Re
Mo mo On ko je da mi
Ogo foko Re.

3 mf Y'o dahun gbogb' adura


Jeka bere ni 'gbagbo
Emi Re nran ni lowo
Ogo foko Re

4 mf Y'o dahun gbogb' adura


Wa sibi ite anu
O ri idaniloju
Ogo f'oko Re
Amin
636
8.7.8.7.8.7.
Oluwa li Oluso-agutan mi. OD 23:1

1 f Jesu l'Olusagutan mi,


Nje k'iberu lo jina
Lowo kiniun at' ekun,
Lowo eranko ibi,
Yio so agutan Tire,
Jesu y'o pa Tire mo.

2. Nigb' ota fe lati mu mi,


On ni; Agutan mi ni,
p O si ku, lati gba wa la;
Jesu ife kil' eyi?
Isegun ni ona Tire,
Ko s' ohun t' o le se e.

3 Lona iye l' o ndari mi,


Let' isan t'o nsan pele;
Ninu oko tutu yoyo,
Nib' ewe oro ki hu,
Nibe ni mo gbolohun Jesu,
Nibe l'o m' okan mi yo.

4. p Gba mo ba nlo s' isa oku,


B' eru tile wa l' ona,
Emi ki o berukeru,
Tor' Olusoagutan wa,
f Gba mo r'ogo at' opa Re,
Mo mo p'agutan Re yo.
Amin.
637
C.M
Abrahamu si pe oruko ibe na ni Jehofa-jire. Gen. 22:14

1. mf Ko to k' awon mimo beru,


Ki won so reti nu;
Gba won ko reti ranwo Re,
Olugbala y'o de.

2 Nigbati Abraham mu obe,


Olorun ni' duro'
Agbo ti o wa lohun ni,
Y'o dipo omo na.

3. p Gba Jjona ri sinu omi,


Ko ro lati yo mo;
Sugbon Olorun ran eja,
T'o gbe lo s' ebute.

4. B' iru ipa at' ife yi


Ti po l' oro Re to,
Emi ba ma k' aniyan mi,
Le Oluwa lowo ,

5. f E duro de iranwo Re,


B' tile pe, Duro,
B' ileri na tile fale
Sugbon ko le pe de
Amin
638
8.8.8.D
Nitori ti itara ile re ti je mi tan.

1. mf Fun mi n' igbagbo to le so


Oke giga di petele;
Fun mi ni ife adura,
Ti nfe lati tun ' le Re ko;
cr K' ife Re bori okan mi,
Ko si gba gbogb' emi mi kan.

2. mf Mo nfe ife to lagbara,


Mo nfe itara to gbona,
cr Ki nyo elese n' nu ina,
Ki nja won lowo iparun,
Ki ndari won sod' Olorun
Ki nf' eje Jesu pa ' na won.

3. mf Mo fe ra ' gba to lo pada,


cr Ki npe laye nitorina ,
Ki nlo ara mi fun awon
Ti ko ti mo Olugbala;
Ki nf' ipe mi han lara won,
Ki nsi ma kik' ife Re.

4. mf Gba ebun ati ise mi


S' owo rere Re, Oluwa;
Jeki nma wasu oro Re
cr Ki nwa laye fun ogo Re,
Ki nlo gbogbo akoko mi
N' ikede Ore elese.

5. mf Bus' okan mi , mu ko gbona,


K' o si f' ife mimo kun un;
cr Beni un o lo gbogbo' pa mi,
Un o f' itara Tire won;
Un o si to won si iha Re,
Awon agutan t' o ku fun.
Amin
639
C.M
E ma sanu awon elomiran, E ma gba awon elomiran la Juda 1:22-23

1. mf A ni' se to logo kan se,


Ise ribiribi;
Ki gbogbo aye dapo mo wa,
Lati se ise na.

2. mp Banuje kun opo ile,


T' alafia ko si;
cr Je k' a f' ayo kun ' le wonyi,
K' a f' Olugbala han.

3. p Eru o ti po yi wa ka,
Won nyira n' nu egbe;
cr Je k' a da ewon t' o de won
K' a pa ibi na re.

4. p Opo aya pelu iya,


Nsokun fun 'banuje;
cr Je ki a tu won ni inu
Pe, ireti si mbe.

5. p Opolopo l' awon omo


Ti mbe ninu ese;
cr Je k' a yo won ninu okun
Si inu imole.

6. f Je k' a wo ihamora wa,


Olorun n' ipa wa,
On l' o nsamona ogun wa,
Si segun t' o daju.
Amin.
640
7.7.7.7.
Ki ife ara ki o wa titi .Heb. 13:1

1. mf Jesu, Iwo ni a nwo,


K' a repo l' oruko Re;
Alade alafia
Mu k' ija tan l' arin wa.

2. Nipa ilaja Tire


p Mu idugbolu kuro;
Da wa po ni isokan;
F' itegun Re sarin wa.

3. f Je k' a ni okan kan


K' a se anu at' ore;
K' a tutu l' ero, l' okan
Gege bi Oluwa wa,

4. f K' a s' aniyan ara wa;


K' a ma r' eru ara wa;
K'a f' apere fun ijo,
B' onigbagbo ti gbe po.

5. f K'a kuro ni ibinu,


K' a simi le Olorun;
K' a so ti' bu ife
At' ogo iwa mimo.

6. f K'a f' ayo kuro l' aye,


Lo si ijo ti Orun,
K' af' iye angeli fo,
K' ale ku b' eni mimo
Amin
641
C.M
E ma ru omonikeji nyin , ki e si fi be mu ofin kristi se. Gal.6:2

1. f Alabukun ni fun ife


Ti ki o je k' a ya;
Bi ara wa jina s' ara,
Okan wa wa l' okan.

2. mf Da opo emi s' ori wa,


Ona t'o la la nto;
Nipa ti Jesu ' la si nrin,
Iyin Re l' a nfi han.

3. Awa ba ma rin l' ona Re,


K' a ma m'ohun kan;
K'a ma fe' hun kan bikose
Jesu t' a pa fun wa.

4. f K' a sun mo O girigiri


Ati si ona Re;
K' a ma r' ore gba lodo Re,
ff Ekun ore- ofe.
Amin.
642
C.M
Kiyesii, o ti dara, o si ti dun to fun
awon ara lati ma jumo gbe ni irepo.OD. 133:1

1 f Wo b' o ti dun , t'o si dara


Lati gbe ni repo;
Be l' o ye fun awon ara
Lati jumo o gbe po.

2. O dibi ororo didun


Ni irugbon Aaron;
Kikan re m' aso re run 're
O san s' agbada re.

3. p O dara b' iri owuro


T'o nse s' oke Sion;
Nibi t' Olorun f' ogo han,
Iye anipekun.
Amin.
643
C.M
Sugbon eyiti o tobi ju ninu won ni ife. I kor. 13:13

1. Alafia ni f' okan na


Nibit' ife gbe wa;
Ife ni o tobi julo
Ninu gbogbo ebun.

2. mf Asan ni gbogbo imo je,


cr Asan ni bru wa;
Ese y'o bori okan wa
B' ife ko si nibe.

3. Ife l' ondari ese wa


Si ona igboran;
Esu mo yi o nwa riri;
Tori ko le n' ife.

4. Ife nikan ni y'o r' opin


Igbagbo on ' reti;
Nipa re l' a o ma korin
Loke orun lohun.

5. K'a to pa ago ara ti


Ile okunkun yi;
Iye ife y'o gbe wa fo
Lo ri Olorun wa
Amin.
644
S.M
Iji awon ti o gbagbo si wa li okan kan ati inu kan. Ise A. 4:32

1. mf A wa yin ife Re
To so okan wa po.,
T' njumo n' idapo didun
Bi won ti nse loke.

2. Nib' ite Baba wa,


f A nf' itara bebe;
A njumo so edun wa fun,
A si nr' itunu gba.

3. mp A mb' ara wa kedun,


A mb' ara wa y' ayo;
Ohun kohun t'o wu ko de,
A si njumo f' ife pin.

4. mp B' ipinya ba si de,


O mba wa ninu je;
mf Ibi kan wa fun idapo
Ti ore nri ' ra won.

5. mp Eyi n' ireti wa,


Ti nso wa ninu je;
f Pe ao pade lai pinya mo
L' ese Jesu l'oke.

6. f Ao bo low' aniyan,
Ao bo lowo ese,
Ife pipe y'o so wa po
Titi ayeaye .
Amin
645
C.M
Gbogbo nwon fo okan kan wa nibi kan Ise A .2:1

1. mf E je k' a yin Olugbala


T'o da wa po l'okan ,
T'o pase k' a tun jo pade,
Lati wa oju Re.

2. O pase k' agbe 'ra wa ro;


Awa jumo nlepa
Ipe giga wa t'o logo,
N' nu isokan emi.

3. cr Ebun t' O fun wa, lokokan,


L' awa nfi ayo lo;
Or-ofe na nsan larin wa,
Ninu ife mimo.

4. cr Ero at' oro wa j'okan ,


Ife wa si j'okan ;
Awa wa n' irepo pipe
Li oruko Jesu.

5. A nse ajopin ayo wa,


At' alafia wa,
Alafia t' aye ko mo,
Ayo t'a ko le so.

6. B' idapo wa ninu Jesu


Ba dun bayi laye,
f Ayo wa y'o ti tobi to
Gba ba yi te Re ka;
Amin
646
8.8.8.D
.O ti dara o si ti dun to fun awon ara lati ma jumo gbe ni irepo.OD 133:1

1. f O ti dara to lati ri
Awon ara ni irepo,
T' ero at' oro won j okan,
Ti won nfi gbagbo at' ife
Jumo nwa ohun ti Orun,
Won nkede okiki Jesu.

2. mf Olorun, Olore -ofe,


T' mu Re dun s' isokan wa,
On f' ayo busi' pade wa;
O n'f' itura mu wa soji
O nyu' bukun Re sori wa,
On fun wa n' ibale okan.

3. mf Jesu, okuta igun 'le


Jek' awon t' Emi Re dapo
Ma wa n'nu isokan pipe;
Jek' a ma gbe nu Emi Re.
K'a f' apere sokan mimo;
Lele fun ijop Re nihin.

4. f Jek' a ma fi mo ara wa
F' ebun or-ofe Re fun wa
Lati ma ya si mimo;
Titi ao f' d' eni pipe,
T' ao ba awon t' oke pad,
T' ao si ni ipo lodo Re
Amin.

647
6.6.6.6.8.8.
Kiyesii, o ti dara, o si ti dun to fun awon ara lati ma jumo gbe ni Irepo.OD. 133:1

1. mf Wo b' o ti dara to
Lati wa l'alafia;
Eso ododo yi
f Nigbat' ara n' irepo,
Ayo isokan ti dun to.

2. Nibiti' sokan wa,


Nibe l' ore-ofe
Ntan si ohun gbogbo,
O si nya si mimo;
O nwa s' okan ti nreti re,
O si nfun- ni lohun t' orun.

3. mf Lojumo l'a nri


Or ofe titun gba;
f Iri bukun ti nse
Sor' oke Hermoni;
O nse sori nu ebun ara wa,

4. cr Nisiyi, Oluwa
Nro ojo ibukun
Pelu itura Re;
Ti nmu okan soji;
Akoro at' arokuro,
Ife Olorun at' eniyan.

5. Ipejopo ara
Ti nwa alafia,
Li on se ilrei
Lati fi ire fun;
mf T'o fi opo re-ofe Re;
F' awon t'o pejo l' oko Re.

6. f O nf' ekun ore Re


Fun awon t'o pejo
Awon ara Sion,
Omo- bile orun
O nfi isura Re fun Won,
Ati iye ainipekun
Amin,
648
7.7.7.7.
E wa , e je ki a korin si Oluwa. OD.95:1

1. mf E wa , e jek' a jumo
F' orin mimo yin kristi;
K'a f'ohun kan fi ogo
Fun Oluwa gbogbo wa.

2. f K' a gb' okan at' ohun wa


Soke bi t' aye ' gbani;
K'a bere ayo orun;
K'a s' ajo ase -ife.

3. A ngbiyanju n'nu ife;


cr Jek' ina ife soji,
Ti njo n'nu awon martyr
T' oku n' tori' Olorun.

4. Awa le ni fe bi won,
Ale pin n'nu ayo won,
A gba wa lowo binu,
Nipa igbagbo kanna.

5. f A nkorin iyin Jesu,


Okanna l' ana , l'oni;
Okanna nigbagbogbo.
Olore -ofe julo.

6. A duro f' Oluwa wa


Bi ' mole ni' le okun;
A jewo Jesu t'o ku
A jewo eleri Re.

7. f Eleri pe, krist' ti ku,


A kan awa Re mo gi,
Krist' ti da ide iku.
Emi iye Re l'a nmi;

8. f Krist' ti goke lo s' orun,


On ni ife wa nfa si;
O wa l' otun Olorun;
Nibe l' ao ba joba
Amin
649
8.7.8.7.&.Ref.
Oluwa, Iwo ni ipin mi.OD. 119:57

1. mf Kristi ni ipin mi titi


On l' o ngba mi nin' ese,
O je ona igbala mi,
f Eri yi wa l' okan mi,
Eri yi wa l'okan mi,
(Low'ese)
ff Mo l'ayo laysa Re,
Or-ofe Re gba mi,
Wri yi si wa lokan mi
(L'okan mi)

2. mf On ni odi agbara mi,


Amona odi at' Oba mi
On si ni Olupamo mi
Nje mo ' le f' ayo korin.

3. f Iyin fun ni t' o ra mi,


Iyin f' Eni ti a pa,
Nje emi bo , Aleluya;
Iyibn fun oro 'yanu.
Amin.

650
14.10.8.8.15.10.
Nitori ojo wa gbogbo nyipo lo ninu ibinu Re awa nlo ojo wa bi ala ti a nro. OD.90:9

1. p A koko wa gbogbo l'o nyara sure koja lo


Won kun fun igba are on 'rora,
mf Sugbon' fe Olorun npo si,
B' nko tile fo ohun okan mi nso inira na;
Un o sunmo Olorun, un mo O.

2. mp Iseju kokan nsun mi mo igbati un o pinya


Pelu aye t' o se owon fun mi
Iri ile si nhun si mi,
Ranti orun s' owon fun mi
Ju ti aye pelu gbogbo ogo ati oro re,
Un o sunmo Olorun ,un o sunmo O.

3. mf Eni’ rapada Oluwa, e korin igbagbo


E fi ara ti oro Olorun,
E duro n’nu ileri Re,
Bi abo e sa abo Re
f Fi igboya rin ona t’ awon ajerku ti rin
Un o sunmo Olorun, un o sunmo O.
Amin.
651
7.4.7.4.6.6.6.4.&.Ref.
Lati isisiyi lo a fi ade ododo lele fun mi. 11Tim. 4:8

1. f Emi y’o d’ ade wura


Gba mba dele;
Un o bo lowo aniyan
Un o wo aso ogo
Em’ o korin itan,
Ti Jesu t’ o ra mi
Gba mba dele
ff Gba mba dele,
Gba mba dele 2ce
Ibanuje y’o dopin)
Gba mba dele)

2. f Okunkun ko ni si mo
Gba mba dele;
Un o bo si imole nla
Gba mba dele;
Imole lat’ oke,
Si ipa ona mi,
Ti y’o ma to lo
Titi dele.

3. f Un o r’ oju Oluwa mi,


Gba mba dele;
Un o korin ore ofe
Gba mba dele
Un o duro n’waju Re.
Un o si ma juba Re
` Titi lae lodo Re
Gba mba dele.
Amin.
652
C.M
Latiisisiyi lo a fi ade ododo lele fun mi 11Tim4:8

1. mf Iro ayo t’ Ihin rere;


Krist’ y’o han ninu mi
Ani emi y’o r’ oju Re.
Un o di mimo nihin.

2. Okan yi y’o je ile Re;


cr Mo gbolohun Emi Re
Wipe, loto, mo mbo kankan
On ki se eleke.

3. mf Ade ogo ti ododo


Ti mo now niwaju,
Gba m’ba segun lagbara Re
Un o gbamu, un o si de.

4. f Mo f’ ayo wo ile leri


Lati oke pisga,
Ireti mi ki o saki
Ireti t’ o logo.

5. cr O mbe ago amo yi wo,


O ngbon ‘ le ti y’o gbe;
Mf Krist’ ba je wa l’oj’ ayo yi,
Sinu tempili Re.

6 Mmo mo pe o wa pelu mi,


cr Sugbon eyi ko to
A fi b’ o le kun okan mi,
Mule li okan mi,

7. mp Olorun mi, f’ ara Re han,


Kun gbogbo afo yi;
Iwo l’ o le kun okan mi,
Ma bo , Olorun mi.
Amin.
653
6526.4.6.7.7.&.Ref.
E fi okan nyin bale nitori ipadawa Oluwa ku si dede. Jak. 5:8

1. mf Jesu le de loni
Ojo ayo;
f Un o si ri Ore mi,
Gbogbo wahala y’o tan
Bi Jesu ba de loni.
f Ojo ayo;
Ojo nla Ologo,
Mp Un o fi suru duro d’ ojo na
Laipe un o ri Oluwa mi
f Ojo ayo
Ojo nla Ologo.

2. mf Boya un o lo loni
Ojo ayo;
f Dabi eni ngb’ ohun
Orin awon ayanfe
Bi pe loni ni un o lo

3. mf Emi o se kanju
Ojo ayo
f Eru ji ko ba mi
Mole tan l’ ebute na
Nitori O wa n’ tosi.

4. mf Un o ma je Oloto,
Ojo ayo
f Un o si ma kede Re,
Bi mo ti feran Re to,
On l’ ohun gbogbo fun mi.
f Ojo ayo
Ojo nla Oloto.
Mp Un o fi suru duro d’ ojo na
Laipe un o ri Oluwa mi
f Ojo ayo
Ojo nla Ologo.
Amin.
654
8.8.88.8.8
Won nyo niwaju re gege b ayo ikore. Isa. 9:3

1. mf Oluwa ‘kore Wo l’a yin;


Ileei Re ‘ gbati ko ye
Orisi igba si nyipo,
Ododun kun fun ore Re;
L’ojo oni, awa dupe;
Je k’ iyin gba okan wa kan.

2 mf B’ akoko ‘rugbin mu wa yo;


B’ igba erun nmu oru wa;
Gbat’ owo ojo ba nrinle;
Tab’ igbati ‘ kore ba pon,
f Wo Oba wa l’a o ma yin;
Wo l’alakoso gbogbo won.

3. f Ju gbogbo re lo, nigbati


Owo re fun opo kale
Gbati ohun ayo gb’ ile
B’ eda ti nko ire won jo;
ff Awa pelu y’o ma yin O
Oore Re ni gbogbo wa npin.

4. mf Oluwa ‘ kore, Tire ni


Ojo ti nro, orun ti nran;
Irugbin ti a ngbin sile,
Tire l’ogbon ti nmu dagbal;
Otun l’ ebun Re l’ ododun;
Otun n’ iyin Re l’ enu wa.
Amin.
655
7.7.7.7
Eniti nfi ekun rin lo, ti o si gbe irugine lowo, loto yio fi ayo pada wa, yio si ru iti re. OD.
126:6

1. f Wa, eyin Olope wa,


Gbe orin ikore ga
Ire gbogbo ti wole
K’ otut oye to de;
mf Olorun Eleda wa,
f L’ o ti pese f’ aini wa;
Wa k’ a rele Olorun
Gbe orin ikore ga.

2. mf Oko Olorun l’a je


Lati s’ eso iyin Re
Alikama at’ epo,
Ndagba f’ aro tab’ ayo
cr Ehu su, ipe tele
Siri oka si kehin;
p Oluwa ‘ kore mu wa
Je eso rere fun O.

3. mf N’ tori Olorun wa mbo


Y’o si kore Re sile;
On o gbon gbogbo paNTI
Kuro l’ oko Re njona;
Y’o f’ ase f’ awon angel’
Lati gba epo s’ ina;
Lati ko Alikama
Si aba Re titi lae.

4. Beni, ma wa, Oluwa


Si ikore , ikeyin
Ko awon eeyan Re jo
Kuro l’ ese at’ aro;
So won di mimo laelae
Ki won le maa ba O gbe
Wa t’ iwo t’ angeli Re
Gbe orin ikore ga.
Amin
656
8.7.8.7& Ref.
Ojo ibukun yio si ro. Esek. 34:26

1. mf O jo ibukun y’o si ro’


Ileri ife itura l’ eyi
Ao ni itura didun
Lat’ odo Olugbala
Ojo ibukun ,
Ojo ibukun l’a nfe,
Iri anu nse yi wa ka
Sugbon ojol’a ntoto.

2. f Ojo ibukun y’o si ro’


Isoji iyebiye;
L’ ori oke on petele
Iro opo ojo mbo.

3. f Ojo ibukun y’o si ro’


Ran won si wa, Oluwa;
Fun wa ni itura didun
Wa f’ ola fun oro Re.

4. f Ojo ibukun y’ o si ro
Iba je le ro loni;
B’ a ti njewo f’ Olorun wa
T’a npe oruko Jesu.
ff Ojo ibukun,
Ojo ibukun l’a nfe;
Iri anu nse yi wa ka
Sugbon ojo l’a ntoro.
Amin.
657
7.6.7.6.D.&. Ref
Niwon igba ti aye yio wa, igba irugbin ati ikore ki yio dopin. Gen. 8:22.

1. A roko, a funrugbin
Sinu oko gbogbo,
cr Sugbon owo Olorun
L’o mu rugbin dagba;
O ran out at’ oru
Lati mu eso pon,
Efun ati orun,
At’ ojo t’ o rinle.
Ebun rere gbogbo
Lati orun wa ni;
Sope f’ Oluwa, esope
Fun gbogbo ife Re.

2. f On nikan li Eleda
Orun ati aye;
O mu itanna tan l’ewa,
O mu irawo tan;
O mbo awon eye;
Papaa awa omo lojojumo.

3. f Baba , a sope fun O,


F’ ohun rere gbogbo ,
Fun ‘ gba rugbin on ‘ kore
F’ emi ‘ lrea, onje;
Gba Ebun tri a mu wa
Fun isegun ife
Si gba okan ope wa,
Wo sa bfe eyi ju.
Amin
658
7.6.7.6.
A fungin kan jade lo lati funrugbin.Mat.13:3

1. cr A gbe lo fun ‘ rugbin re;


Rugbin si farasin
Ojo pupo l’ o koja
Ki o to ru jade;
Oorun ti nran mu gbona,
Ojo si mu dagba,
Oko pon fun fun ikore
Loju wa leekan si,
f Yin A fungbin t’orun
T’ o fi eso fun wa
T’o bomiran lakoko
T’o si mu pon fun wa.
2. f Wo Afungbin t’ orun
Nlo furugbin iye
O nf’ owo at’ ese Re
Fon oro igbala,
Laarin Ijo Re nihin,
Okan wa l’oko Re
mp E jek’ a s’ eso pupo
Fun ere laalaa Re
Kore na y’o ti dun to
T’o kun f’ opo ire,
Eyi l’ope otito,
Akoso aye wa.

3. mf Jesu nfungbin miran


Sinu ile mimo,
Gbati ile gba oku
Awon ti on ku fun;
f B’ a ko tile le ri won
A mo ope won y’o ji;
O daju pe won wa ni
ff Paradise ayo,
Ile ikore t’ o kun
F’ awon eni- mimo
Ti won wo ewu kristi,
Ti won d’ ade wura;

4. cr Afungbin ti orun
Y’o kore ijo kan,
f Y’o si f’ s ‘ayo pada wa
Pelu awon Tire;
Gbana y’o ileru ina
mp Iwo Olukore nla,
Saanu wa l’ojo na
T’ Iwo y’o o se ikore ,
Ma si se ta wa nu .
Amin

659 8.7.8.7.D.
Emi ko pa iseun ife Re ati otito Re kuro lodo ijo nla ni.OD.40:10.

1. f Oluwa, a gbe okan wa


Si O’n’ nu orin Iyin;
A m’ ore ope wa fun O
Pelu iho ayo nla;
Gbogbo papa f’ ewa bora
Awon oke nho f’ ayo
Oka po l’ afonifoji
Tobe ti won fi nkorin.

2. mf Loni, ojo ikore wa


Awa jewo ore Re,
f Awa f’ ope mu ebun wa,
Akoso ibukun Re
Wo l’ o nfi ore –ofebo
Okan awa eda Re,
Wo ti pese onje o jo,
Fi onje orun bo wa,

3. cr A nfarada oru ojo,


Laalaa a si ma su – ni;
mf Sugbon nigbati oorun wo
‘Simi de fun a;laare;
mp Se wa l’ eni itewogba,
Gbat’ angeli ba nkore,
K’a je alikama kristi
Ti on y’o to si aba.

4. mf Abukun n’ile Olorun


Bit awon mimo wa lae
Papa wura teju nibe
Odo re bdan bi kristal,
ff Orin egbe mimo t’ ohun
Dapo mo tiwa loni;
Bukun orin ‘ kore na po
Ti a o maa ko titi.
Amin.

660
6.5.6.5.Triple
Ojo oni ni yio si ma se ojo iranti fun yin enyin o sima se li ajofun Oluwa.. Eks. 12:L14

1. f A dupe Oluwa
F’ ajodun oni
O da emi wa si,
Ogo f’ oko Re;
ff Pelu orin ayo
L’a o fi Josin
Fun’ bukun aye wa
On reti orun.
ff Ajodunde, eyo
Ke, Aleluya
A m’ ore ope wa,
Tewo gb’ ore wa.

2. mp Opo l’elegbe wa
Ni ko tun si mo;
Opo ti sako lo
Kuro lodo Krist’
f A dupe Oluwa
Pe O da wa si,
O si tun ka wa ye
F’ ajodun oni,

3. mf Baba wa li orun,
Awa se ‘ pinu
Pe a o sin Jesu
L’ojo aye wa,
A o sise fun’ dagba
Soke ijo wa,
Tit’ ao fi je ‘ pe Re
Fun ‘ simi orun.

4. mf Wo Oluw’ ajodun
A f’ ope fun O
di Je k’ ire ajodun
Kari gbogbo wa;
A be O, Olorun,
Fun wa l’ agbara
Lati sin O d’ opin
Ojo aye wa.
Amin.
661
6.6.6.6D.
Awon enia mimo Re yio si ma fi ibukun fun O. OD.145:10

1. f Ogo, iyin , Ola,


Fun Olugbala wa
T’o da emi wa si
Titi d’ ojo oni
Ayo kun okan wa
Fun anfani nla yi
Lati sise fun O
N’nu ogba Re laye.

2. f A dupe fun ‘ toni


On agbara t’ emi
At’ ebun ife nla
Ti o fi so wa po,
Olusagutan wa,
Tewo gba iyin wa;
Nitori anu Re
Se wa l’ okan laelae.

3. mp Bukun wa, Oluwa,


Loni ajodun wa,
Ran ami Re si wa
K’a layo n’nu sin Re
Ka si a;seyori
N’nu ise isin wa
K’a si fi Jesu se
Igbekele wa lae.

4. mf Eleda, Oluwa,
Orisun ‘gbala wa,
di Se wa ye f’ ajodun
Ti ibugbe loke;
N’ pari ajo wa
N’nu aye osi yi,
K’ale ni ibugbe
Lodo Re Oluwa.
Amin
662
8.8.8.4
Nitori ohun gbogbo odo Re ni o ti wa, ati ninu ohun owo Re li awa ti fi fun O 1kor.29:14

1. f Oluwa orun ayem,


Wo n’ iyin a’ ope ye fun,
Bawo la ba ti fe O to
Onibu ore.

2. Orum, at’ afefe,


Gbogbo eweko ,nso ‘ fe Re;
Wo Onibu yin ore.

.3. Fun ara lile wa gbogbo,


Fun gbogbo Ibukun wa
Gbogbo ibukun,aye
Wo l’ O nmu irugbin dara,
Onibu Ore..

4. p O fun l’ o ofe l’o nfun


O fi du wa li Omo Reyi.
Pelu l’ Rec l’o nfun wa
L’ ohun gbogbo.

5. mf O fun wa l’ Emi mimo Re/.


Emi iye at’ agbara,
O ro jo ekun ‘bukun Re
Le wa l’ori.

6. p Fun idariji ese wa,


cr Ati fun ireti orun,
f Kil’ ohun t’ a ba fifun O
Onibu ore.

7. Owo ti nna ofo ni,


Sugbon eyi t’a fi fun O,
O je isura tit aye,
Onibu ore.

8. Ohun t’ a bun O, Oluwa


cr Wo O san le pada fun wa,
f L’ayo l’a ta O lore
Onibu ore.

9. Ni odo Re l’a ti san wa,


Olorun Olodunmare,
Je k’ a le ba O gbe titi;
Onibu ore.
Amin.
663
8.6.8..6.8.8.8.6.
Ife ni Olorun. 1Jn. 4:8.
1. f E wa k’ a jo jumo korin,
Ife ni Olorun
Orun, aye mu yin won wa
Ife ni Olorun
Ki gbogbo okan ji kuro
Ninu ese ki won f’ ayo
Korin didun n’ tori Jesu,
Ife ni Olorun.

2. E so ni gbogbo abaye
Ife ni Olorun
N’nu krist’ l’ ekun ‘ rapada wa
Ife ni Olorun
Eje Re le w’ ese wa nu,
Emi Re s’ oru wa d’ osan
O nto’ kan wa lati so pe
Ife ni Olorun.

3. Ayo ni ipin wa nihin


Ife ni Olorun
Okan wa nyo si’ leri Re
Ife ni Olorun
Orun at’ abo wa losan
O si mba wa gbe mi oru
On yo wa pelu wa titi
Ife ni Olorun.

4. Ni Sion lao tun korin yi


Ife ni Olorun
ff Orin t’ yo ga soke julo
Ife ni Olorun
Titi aye anipekun
Pelu awon mimo loke
Orin wa to dun julo ni;
Ife ni Olorun
Amin.
664
11.8.11.8.
Emi mi si yo si Olorun Olugbala mi Lk. 1:47

1. mp Iwo, niwaju enit’ okan mi nyo


Ti mo npe nigba iponju,
Tunu mi l’ osan at’ orin mi l’ oru
Reti at’ igbala mi.

2. mp Nibo l’o nko awon agutan Re lo,


Lati f’ onje ife bo won,
Ese ti un o fi sokan li anidi
Tabi nikan rin l’ aginju?

3. mp O siju wo, opo angeli si yo,


Pupo si duro d’ oro Re;
O soro, ayeraye si gb’ ohun Re,
E korin iyin s’ Oluwa.

4. mf Olugbala emi y’o je ipe Re,


Emi mo adun ohun Re;
Pa mi mo tori Iwo ni gbogbo mi,
Un o ma yo ninu Re titi.
Amin.
665
8.6.8.6 & Ref
Sugbon emi gbekele le O Oluwa; Emi ni ,.Iwo ni Oloun mi.OD.31:14

1. mf Jesu, mo gbekele mi le O;
Ife Re si mi ti po to;
Iwo l’ agbara emi mi,
f Tire nikan l’emi,
Loni titi lae;
O feran mi Oluwa
Eyi da mi loju.

2. mf Ife o fi npase Tire,


Owo jeje l’o fi nto ni;
Otito Re ni mo di mu,
Eyi da mi loju.

3. mf Mo mo pe un o wo nu ogo,
Un o ma gbe nu ile didan;
Igbagbo lilo y’o dopin.
Eyi da mi loju.
Amin.

666
8.7.8.7.
Oluwa lo Oluso-agutan miOD.23:1

1. f Jesu l’Olus’ agutan mi,


Ore Eni tio ki ye
Ko s’ ewu bi mo je Tire,
T’o si je t’ emi titi.

2. f Nib’ odo omi iye nsan


Nibe l’O nm’ okan mi lo;
Nibiti oko tutu nhu,
L’O nf’ onje orun bo mi.

3. p Mo ti fi were sako lo,


cr N’ ife O si wa mi ri;
di L’ejika Re l’ O gbe mi si,
f O f’ ayo mu mi wa ‘le.

4. p Nko beru ojiji iku,


cr B’ iwo ba l’ odo mi;
Ogo Re ati Opa Re
Awon l’ o ntu mi ninu.

5. mf Iwo te tabili fun mi;


Wo d’ ororo s’ ori mi;
A’ ayo na ha ti po to
Ti nt’ odo Re wa ba mi?

6. f Be l’ojo aye mi gbogbo


Orre Re ki o ye lae
Olus’ agutan, un o yin O
Ninu ile Re titi.
Amin.
667
9.6.9.8.&.Ref.
Sugbon On mo ona ti emi nto.Jobu 23:10

1. mf Mo l’ope kan lo wa nitosi


L’ osan ati l’oru,
O nfi oju Re so mi titi
O mo ona ti emi ngba.
f O mo ona ti emi ngba,
O si npa mi mo l’ osan , loru
O nto mi li oruko Re,
O mo ona ti emi ngba.

2. mf Mo ni ore kan t’o sunmo mi


Ko je mi sile;
Bi ona tile s’ okunkun
O mo ona ti emi ngba.

3. mf Mo l’ore kan ti y’o ma to mi


Tit’ opin y’o fi de
O nto mi titi un o fi d’ ade
O mo ona ti emi ngba.
Amin.
668
7.6.7.6 &Ref
Mu okan iranse Re yo nitori Iwo Oluwa ni mo gbe okan mi s'’oke si.OD.86:4

1. Okan ayo mi nko’ rin


Ife Baba orun;
O ran opo ibukun,
B’ orun lat’ oke wa
ff Sugbon Jesu----- l’ O san jule------
(Jesu l’ o san ju)
Be ni Jesu--------- l’ O san julo------
(Jesu l’O san ju)
N’nu gbogbo-------- ti o yi mi--------ka
(Ninu gbogbo ayo ti o yika tio yika)
Jesu nikan l’ O julo.

2. mp B’ ayo miran gbogbo pin,


Ti banuje si de,
mf Jesu yio pelu mi,
On si dara julo.

3. mf Un o so fun elomiran
Itan or’ ofe Re;
Un o ma yo n’nu isin Re
Titi un o r’oju Re.

4. f Gba mo ba si ri ogo
Ninu odi Jasper;
Un o ko ‘rin irapada,
P’Olugbala san ju.
Amin.
669
D.C.M
Awa feran Re ; nitori On li o ko feran wa Ijn.4:19

1. mf Jesu Oluwa a fe O
Tori gbogbo ebun
Nt’ owo Re da lat’ oke wa
B’ iri si gbogb’ aye;
A yin O n’tori wonyi,
K’ ise fun won nikan,
Ni awon omo-odo Re
Se ngb’ adura si O.

2. p Awa fe O, Olugbala,
Tori’ gbat’ a sako,
Iwo pe okan wa pada
Lati t’ ona iye;
Gba t’ a wa ninu okunkun,
Taa ri ninu ese,
cr Wo ran imole Re si wa
Lati f’ ona han wa.

3. f Baba orun awa fe O,


Nitori’ wo fe wa
Wo ran omo Re lati ku,
Ki awa le n’ iye;
Gbat’ a wa l’ abe binu Re
Wo fun wa n’ ireti;
cr Bi l’o ndariji wa.
Amin.
670
7.7.7.D.
Nje ntoriina , ara ajigbese li awa.Rom8:12

1. mf Gbat’ aye yi ba joja,


Ti orun re ba si wo
Ti a ba wo ‘nu ogo,
T’ a boju wo ehin wa,
f Gbana, Oluwa, un o mo
di Bi gbese mi ti poi to.

2. f Gba mo ba de b’ ite Re.


L’ewa ti ki se t’ emi,
Gba mo ri O b’ o ti ri,
Ti mo fe O l’a fe tan;
Gbana Oluwa un o mo
di Bi gbese mi ti po to.

3. f Gba mba gbo orin orun,


T;o ndun bi ohun ara,
Bi iro omi pupo;
P T’o si ndun b’ ohun duru,
mf Gbana Oluwa , un o mo

4. mp Oluwa jo , je k’a ri
Ojiji Re l’aye ti,
P K’a mo adun b’ ohun’ dariji
Pelu irawo Emi.
cr Die ninu’ gbese mi.

5. mf Ore –ofe l’o yan mi,


L’o yo mi ninu ewu
P Jesu l’ Olugbala mi
Emi so mi si mimo;
cr Ko mi ki nfi han l’ aye,
Bi ‘gbese mi ti po to.
Amin.
671
.7.7.7
Iwo fe mi bi ? Jn 21:16

1. mf O kan mi, Oluwa ni,


Jesu ni, gb’ oo Re,
Jesu nso, O mba o So,
P Pe elese’ wo fe ni?

2. mf Gba t’ a de o mo da O,
O gb’ ogbe mo wo o san;
Mo s’ okun re d’ imole;

3. Kike iya ha pin


Si omo re ti I bi/
di L’ otito, o le gbagbe,
cr Sugbon Em’ o ranti re;

4. mf Ife t; Emi ki ye lae,


O ga rekoja orun;
O si jin ju okun lo,
f Ife alailegbe ni,

5. cr Wo fere r’ ogo Mi na.


Gb’ ise ore-ofe tan;
Wo o ba mi gun wa po
P Wi elese, wo fe mi?

6. mp Olori aroye mi
Ni pe ife mi tutu;
cr Sugbon mo fe O jesu,
f A mba fe O ju yii.
Amin.
672
8.8.8.D
E duro ninu ife mi. Jn .15:9

1. mf Jesu Oluwa , oba mi


Gb’ ohun mi nigbati mo npe
Gb’ ohun mi lati bugbe Re
Ro jo ore-ofe sile
cr Oluwa mi, mo feran Re
Je ki nle ma feran Re si.

2. p Jesu mo ti jafara ju
cr Un o se le fe O, b’ o ti ye
Em’ o se le gb’ ogo Re ga
Ati ewa oruko Re
f Oluwa mi, mo feranRe
Je ki nle ma feran Re si.

3. mf Jesu ki l’o ri ninu mi


Ti fe po to bayi?
cr Orer Re si mi ti po to
O ta gbogbo ero mi yo
f Oluwa mi, mo feran Re
Je ki nle ma feran Re si.

4. f Jesu ‘ wo o je orin mi,


Tire l’ aya at’ okan mi
Tire ni gbogbo ini mi
Olugbala, Wo nitemi,
ff Oluwa mi, mo feran Re
Je ki nle ma feran Re si.
Amin.
673
6.4.6.4.&.Ref
Ma fi mi sile , beni ki o mase ko mi Olorun igbala mi.OD17:9

1. mf Mo nfe O n’ gbagbogbo,
Iwo Olore;
K’o s’ ohun bi Tire
T’o m’ alafia wa.
ff Mo nfe O A mo nfe O,
Ni wakati gbogbo;
Bukun mi, Olugbala;
Mo wa s’ odo Re.

2. mf Mo nfe O n’ gbagbogbo;
Duro ti mi;
Idanwo ko n’ ipa
B’ o wa n’ tosi.

3. mf Mo nfe O gbagbogbo;
L’ayo n’ ise,
Yara wa ba mi gbe ,
Asan l’aye.

4. mf Mo nfe O, gbagbogbo ;
Ko mi n’ ife Re
Mu ileri Re se
Si mi l’ara.

5. mf Mo nfe O n’ gbagbogbo,
Eni Mimo,
Se mi n’ Tire toto
Omo ‘ bukun
Amin.
674
7.8.7.8.7.7.8.
Oluwa li Oluso-agutan mi .OD.23:1

1. ‘B Olus’agutan rere.
mf Jesu nto wa, Jesu nto wa,
Si papa oko tutu,
Jesu nto wa, O nto wa
mp Bi ‘ kuku ba bo ona,
T’ ewu si yi agbo ka,
mf Ki y’o je ki won sina,
Jesu nto wa , O nto wa

2. mp Ninu wahala aye,


mf Jesu nto wa , Jesu nto wa,
Titi ao fi de oke,
Jesu nto wa, O nto wa,
O ti rin ona ri,
O si nk agutan Re,
Lo sinu agbo t’ orun
Jesu nto wa, O nto wa.

3. mf Ninu ‘mole aye yi


Jesu nto wa, Jesu nto wa,
L’ arin ogun at’ ija
Jesu nto wa, O nto wa,
cr Gbat’ a ba d’ odo Jordan
Nibiti ajo wa pin,
Y’o si pin omi n’ iya.
Jesu nto wa, O nto wa.
Amin.
675
5.5.8.5.5
Oluwa Olorun mi yiotan imole si okunkun mi OD.18:28

1. mf Jesu, ma to wa,
Tit’ ao fi simi;
Mp Bi ona wa ko tile dan
Ao tele O l’ aifo ‘ya
F’ owo Re to wa.
S’ ilu Baba wa.

2. mp B’ona ba l’ewu,
B’ ota sunmo wa,
Maje k’ aigbagbo m’ eru wa,
Ki gbagbo on ‘reti ma ye,
f ‘Tor’ arin ota
L’ a nlo si le wa.

3. mp Gbat’ afe tunu


Ninu ‘ banuje,
Gbat’ idanwo titun ba de
Oluwa fun wa ni suru;
f F’ lu ni han wa
Nib’ ekun ko si .

4. mf Jesu, ma to wa;
Tit’ ao fi simi
Amona orun, toju wa
Dabobo wa, tu wa ninu,
Titi ao fi de
Ilu Baba wa.
Amin.
676
7.7.7.D
On O pa mi mo ninu ago Re.OD.27:5

1. mp Apata ayeraye,
Se ibi isadi mi;
cr Jeki omi on eje
T’o san lati iha Re
Se Iwosan f’ ese mi,
K’ o si so mi di mimo,

2. mf K’ ise ise owo mi


L’o le mu ofin Re se,
B’ itara mi ko l’ are
T’omije mi nsan titi,
Won ko to fun etutu
Wo nikan l’ o le gbala.

3. p Ko s’ ohun ti mo mu wa,
Mo ro mo agbelebu;
Mo wa k’o d’aso bo mi,
Mo now O fun iranwo;
Mo wa sib’ orisun ni,
cr We mi, Olugbala mi.

4. mp Gbati emi mi ba pin,


p T’ iku ba p’ oju mi de,
cr Ti mba los’ aye aimo,
Ki nri O n’ ite’ dajo;
di Apata ayeraye
pp Se ibi isadi mi.
Amin
677
8.7.8.7.8.7
Iwo o fi imo Re to mi li ona ati nigbehin Iwo o gba mi sinu ogo.OD. 73:24

1. mf Ma toju mi, Jehofa nla,


Ero l’aye osi yi;
Emoi ko l’ okun, Iwo ni
F’ owo agbara di mi mu,
mf Onje orun , onje orun,
Ma bo mi titi laeale

2. cr S’ilekun isun ogo ni;


Orisun Im’ arale;
Je ki imole Re Orun;
Se amona mi jale;
Olugbala at’ asa mi.

3. p Gba mo ba de eba Jordan,


F’ okan eru mi bale,
cr Iwo t’o segun iku,
Mu mi gunle Kenan je;
f Orin iyin, Orin iyin
L’ emi o fun O titi.
Amin.
678
7.7.7.7
Awon agutan mi ki yio segbe Jn.10:28

1. mf Tire laelae l’ awa se


Baba, Olorun ife;
cr Je k’ aje Tire titi
L’aye yi, ati laelae.

2. mf Tire laelae l’ awa se


Ma toju wa l’ aye yi;
Wo iye , Ona , O to,
To wa si ilu orun.

3. p Tire laelae Abukun


L’ awon t’ ose simi won
cr Olugbala, ore wa
Gba ja wa de opin.

4. p Tire laelae Jesu pa


Awon agutan Re mo.,
cr L’abe iso rere Re
Ni k’ o pa gfbogbo wa mo.

5. f Tire laelae Aini wa


Ni o je aniyan Re;
O ti ese wa ji wa
To wa si ibugbe Re. Amin
679 12.12.12.9.&.Ref
Yio pa okan re mo.OD.121:7

1. mf Mo mba rin , mo nba Jesu Oba mi soro


Mo si ni ayo nini’ orin ‘ yin mo nko
f Bi mo ti gbekele si ni ojojumo
Ni o npa mi mo ninu’ fe Re
On pa mi mo ninu ‘ fe Re
Mo si mo , emi o ba loke
Yio so Tire, tit’ ojiji y;o fi lo
O npa mi mo nin u ife Re.

2. mf Mo ni ayo ninu Jesu , nko sina to


Igbadun ti o wa ninu ese lrhin
f Nitori O nfun mi l’ayo l’ojojumo
O npa mi mo ninu ife Re.
3. mf Olurapada mi san ju gbogb’ ore lo,
O ti f’ ese mi ji, O si sure fun mi
f Mo si mo pe ao pade ni Orun ‘ simi
O npa mi mo ninu ife Re.
Amin
680
6.6.6.D.
Jesu wipe ; Iwo o ha fi emi re lele nitori mi. Jn. 13:38

1. mf M o f’ ara mi fun O,
Mo ku nitori re,
cr Ki o le ra O pada,
K’o le jinde n’ noku;
p Mo f’ ara mi fun O,
Kini wo se fun mi.

2. mp Mo f’ ojo aye mi.


Se wahala fun O
cr Ki iwo ba le mo
Adun ayeraye;
P Mo l’ opo’ dun fun O,
O lo ‘ kan fun mi bi?

3. f Ile ti Baba mi,


At’ ite ogo mi,
di Mo f’ sile w’ aye
Mo d’ alarinkiri;
p Mo fi le tori re,
Ki l’o fi le fun mi.

4. Mo jiya po fun O,
Ti enu ko le so,
Mo jijakadi nla,
Mp Mo jiya po fun O,
O le jiya fun mi.

5. mf Mo mu igbala nla
Lat’ ile Baba mi
cr Wa lati fifun O
Ati idariji
Mo m’ ebun wa fun O,
P Ki l’o mu wa fun mi.

6. f Fi ara re fun mi.


Fi aye fun mi.
Diju si nkan t’ aye,
Si wo ohun t’orun;
Mo f’ ara mifun O,
Si f’ ara re fun mi.
Amin.
681
8.7.8.7.8.7.
Emi fi ifoni ayeraye fe O.Jer. 31:3

1. mf I feni ayeraye,
L’ ore- ofe fi fe mi,
Emi Re lat’ oke wa
L’o fi oye na ye mi,
Alafia didun ni
Ti gbe mi kuro l’ aye,
Ife ti ko le tan ni,
Mo je Tire titi lae.

2. f Aye di orun fun mi,


O ndun si lo lojojumo,
Mo nri krist’ nibi gbogbo
Ti awon t’ aye ko ri,
Ninu orin t’ eye nko
Ninu itanna igbe,
Lat’ igba ti mo mo pe,
Mo je Tire titi lae.

3. f Ohun ti mba l’ eru


Ko tun ba mi l’ eru mo,
Labe iye- apa Re,
Nib’ ikok’ Oga ogo;
Nibe ni mo simi le;
Aniyan on ‘yemeji,
Ko duro l’ okan mi mo,
Mo je Tire titi lae.

4. f Tire laelae l’ emi’ se


Tani y’o ya wa n’ ipa,
Isimi wo lo to yi.
Fun okan ti kisti ngbe;
B’ orun on aye koja.
Ti ogo re si parun,
T’ emi t’ Olorun y’o wa.
Mo je Tire titi lae.
Amin.
682
8.7.8.7.8.7
Oju mi yio ma ba lo , emi o si fun o ni isimi.Eks 33:14

1. mp Ma to wa Baba wa orun
Larin ‘ danwo aye yi,
Pa wa mo k’ o si ma bo wa,
A ko n’ iranwo miran,
mf Sugbon gbogbo’ bukun l’ ani
B’ Olorun je Baba wa

2. mp Olugbala, dariji wa
Iwo sa m’ ailera wa
cr Wo ti rin aye saju wa,
Wo mo egbe inu re
Bi alare, Eni kanu
N’ Iwo l’ aginju yi ja.

3. f Emi Olorun, sokale,


F’ ayo orun k’ okan wa,
K’ ife dapo mo iya wa,
At’ adun ti ki su ni,
B’ a ba pese fun wa bayi,
Ki l’ o le da wa lamu.
Amin.
683
9.7.9.7.9.8.9.7.&.Ref.
Lati fi oso fun won nipo eru, ororo ayo ofo, aso iyin nipo emi ibanuje.Isa.61:3

1. mf Mo nkorin ife Olorun mi


Ti Emi Re abe ‘ nu mi.
Eni t’ O ekun mi dayo,
T’o dari ese mi ji.,
mp Bi ikuku tile su dede
mf Y’o wa pelu mi ninu re,
O tan imole s’ okunkun mi
O si nm’ eru mi fuye,
O nso ibanuje mi d’ ayo
O nfun mi n’ ife ti ki sa,
f O tan imole s’ okunkun mi
O si nm’ eru mi fuye.

2. mf Mo nkorin ife Olugbala


Eni t’o jiya fun mi,
Nibi ikoko niwaju Re
O ja gbogbo ide mi
O mu onirobinuje yo
O nfun alare ni’simi,
O si nso omije di erin,
O nmu eru mi fuye.

3. mf Mo nkorin ayo t’ ihinrere


Fun onirobinuje,
Ihinrere ayo at’ erin,
Nibikibi ti mba lo,
Ti mbo aso ofo l’ ara wa
Ti nmu wa ko orin iyin,
f O si nm’ eru mi fuye.
Amin.
684
8.7.8.7.4.7
Ki a si pa emi ati okan ati ara nyin mo patapata li ailabulu. 1Tes. 5:23

1. mf Orisun igbala kikun


Si sile fun gbogbo wa
Lat’ odo Olugbala wa
Lo nsan yi gbogb’ aye ka;
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.

2. mf Iran Ologo li eyi,


Isun iwenumo nsan,
cr O new gbogbo abawon nu,
Ti idale ese;
Eje ti new moi laulau.

3. mf Isun ijinle ife Re


Nsan ni inu okan wa;
cr O new gbogbo ero aimo
K’ a le wa lailabawon,
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.

4. mf Isun iye ainipekun


Lati orun nsan si wa,
f Olorun dapo pelu wa,
Idapo t’o dun julo;
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.

5. f Eru’ banuje ti fo lo
Aniyan on ‘ yemeji,
Igbagbo ko beru ola
Tor’ Oluwa nsamona,
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.
Amin.
685
L.M
Awon orun nsoro ogo Olorun .OD.19:1

1. f T ire, Oluwa, li ogbon,


Ododo mbe li odo Re,
Sibe niwaju ite Re,
Anu l’ o da owo Re ro.

2. Alale nfi ife Re han,


Ororo nf’ ore nla Re han;
Ibinu Re ki tete ran,
Anu Re tan yi aye ka.

3. mf Baba, ore on ‘ toju Re


L’o fun wa n’ iye on ‘ mole,
Ohun t’a ni, ohun t; a je,
Ebun atowo Re ni won.

4. mf Orisun ire, owo Re


L’o nseri’ bukun s’ ori wa,
L’o nf’ onje on ayo f’ awon ,
T’o wa loke , n’ ile, l’okun.

5. f N’ ipa Re ni gbogbo nkan wa


Agbara Re l’’ ogbe won ro;
Papa awon t’ o ngb’ ore Re
Ti won ntapa si joba Re;

6. O pase ki orun k’ o ran,


Bakanna, sori gbogb’ eda
O ro ojo ibukun Re
Sor’ eni re on buburu.

7. mp Awon t’ o gan agbara Re


Y’o r’ ina ibinu Re;
mf Awon ati ade didan.

8. f Tire, Oluwa, n’ ijoba,


Tire ni gbogbo agbara;
Bi gboogbo eda tile ku;
Sibe ogo Re y’o ma tan.
Amin.
686
D.C.M
E tei lele, ki e si wa sodo mi.Isa 55:3

1. Mo gb’ohun Jesu t’o wipe,


Wa simi lodo mi;
cr Wo alare, aya gbe ori re
Le okan aya Mi;
mp N’nu re on ibanuje,
Ni mo to Jesu wa;
mf Lodo Re , mo r’ ibi simi,
 n si mu ‘ nu dun.

2. Mo gb’ohun Jesu to wipe,


cr Iwo ti ongbe ngbe,
Un o f’ omi ‘ ye fun o l’ ofe
Bere, mu ko si ye
Mo to Jesu wa, mo si mu
N’nu omi tutu, o soji
mf Okan mi tutu o soji
Mo d’ alaye n’nu Re.

3. Mo gb’ ohun Jesu to wipe


cr Mole aye l’ Emi;
Wo mi . orun re yo si la.
Ojo re yo dara
Mo wa Jesu n’nu Re mo ri
Rawo at’ Orun mi.
N’nu mole Re l’ emi yo un
Tit’ ajo mu yo pin.
Amin.
687
10.10.11.11
Kili emi o san fun Oluwa ,nitori gbogbo ore re si mi.OD.116:12

1. mf Kini uno fi yin Olugbala mi.,


Eni oloto t’o po l’ or’ ofe,
T’o le fi igbala on irapada
F’ awon onigbagbo t’o gb’okan won l E

2. f Ayo emi t’ a dande ti po to


Awon eniyan na t’ o le yo n’nu Re
Ayo won mi lati rin n’nu’ mole Re,
Sibe nwon nso nipa or’ ofe Jesu.

3. f Won nyo n’nu oko Re lojojumo;


Won nf’ ododo Re s’ ohun eto won;
Eje Re we won n’nu ododo Re.
Laifoya ni nwon o yoju s’ Olorun.

4. f Iwo ni fuja, ogo, ipa won ;


Emi si nreti igba ayo na;
Ti un o di atuni, ti un d’ alaye,
Ojo ‘ gbala ti y’o gb’ ori mi soke.

5. f Jesu Oluwa li abo fun mi;


Ko s’ eni t’o le ja mi lodo Re;
Y’o se ohun gbogbo n’tor’ O feran mi;
Olugbala mi y’o so mi di orun.

6. ff O daju , Jesu un o ri bukun Re,


Aisri Re si fere han fun mi;
Beni y’o ayo dipo banuje;
Un on ‘ipin n’ayo awon t’o gbagbo.
Amin.
688
8.7.8.7.D
Ko si enikan ti o ni ife ti o tobi ju eyi lo pe enikan fi emi re lele nitori awon ore re. Jn.
15:13

1. mf Mo l’ ore kan , ife Re po,


O fe mi k’ emi t’o m’O;
cr Okn ife l’O fi fa mi,
O si de mi mo ra Re;
Koko ‘fe Re t’a ko le tu,
Lo mo okan mi sibe
f Mo je Tire, on temi,
Lae ati titi laelae.

2. mf Mo l’ Ore kan , ife Re po


O ku lati gba mi la;
cr Iye nikan ko l’O fun mi
O fi ara Re ji mi,
Nko ni p’ ohun kan ni temi;
Un o pamo f’ Olufunmi;
f Okan, agbara, emi mi
Tire, ni titi laelae.

3. mf Mo l’ Ore kan , ife Re po


Gbogb’ agbara l’a fi fun
K’ O le so mi li ajo mi,
K’ O si mu mi de Orun
f Ogo ailopin nytan ‘ mole,
Un o sora, un o sise un o ja.
Lehin na, un o simi Lae.

4. mf Mo l’ Ore kan, ife Re po


Oniyonu, Oloto;
Olugbimo at’ Amona,
Alabo t’o lagbra
cr Kini’ ba le ya mi lodo
Eni fe mi po to yi;
Iye, oku aye, egbe
f Beko mo je Tire lae.
Amin.
689
C.M
Oluwa, Iwo ni mo gbe okan mi soke si OD.25:1

1. mp Baba, mo gb’ okan mi si O,


Wo ni mo gbekele;
cr Mo mo daju pe lodo Re
L’ ebun pipe ti wa.

2. mf Tire nikan l’ anu Ore.


Agbara on ogbon;
Li aisi Emi Omo Re
A ko le se re kan.

3. mp A ko s’ oro rere kan,


A ko le ro’ re kan
B’ iwo ko ba sure fun wa
N’ tori oluwa wa

4. O f’ eje Re ra or’ ofe,


Agbara eje na
L o se ‘ ranwo fun iran wa
Ati fun mi pelu.

5. Gbogbo ise rere t’ a nse.


Iwo li O nse won;
f Tire n’ iyin gbogbo ero
At’ oro rere wa.

6. Lat’ odo Re, nipa Jesu


L’ a gb’ ase adura;
N’nu eni ti a mbe laye;
Olodunmare wa.
Amin.
690
8.7.8.7.D
Iwo li o da mi ni ide ninu iponju. OD.4:1

1.. mf Baba orun, Wo l’o mu wa


D’ ojo oni l’ alafia,
Pele l’o nto isise wa
T’o si nf’ iso Re so wa,
f Wo ore at’ Amona wa,
A o le yin O b’ o ti ye
Fun ‘ fe Re ti ki pada

2. mf Bni gbogbo igba t’ o koja


L’a nri anu gba lotun,
Itoju on iseun ife
Ko fi igba kan jin na.
Ife ati aba orun
Mba wa gbe tosan –toru
Ibukun t’ a ko le siro
Ntan imole s’ ona wa.

3. mp N’nu danwo nla l’ a ti ko


Iji ‘ponju ti lu wa;
Idanmu ti sokun bo wa
Tob t’ a ko fi ri O;
mf Sibe ife Re ko ko wa
Sibe n’nu banuje wa
Iranwo t’ a nse f’ ara wa
Nipa agbat’ ajo wa ba ni.

4. pp Opo awon olufe won


Ti de opin ajo won ;
Ara, omo lati pade wa
cr Nigbat’ ajo wa pari.
Ti ai se alaisi,
mf Baba, mu wa la ojun ja
Sinu mole ailopin.
Amin.
691
7.6.7.6..6.8.8
Anu se e.LK. 10:33

1. mf I fe l’o fi wa emi
Ti eru ese npa
O gbe mi s’ ejika Re
Pada bowa s’ gbo
f Angeli nfi ayo korin
Pelu awon ogun orun
ff A ife t’ o wa mi;
A Eje t’o ra mi
Suru pelu ore ofe Re
T’o fa pada bo wa s’ agbo.

2. mp Mo gbogbe, mo fere ku
O tu oror si;
O so fun mi jeje pe;
pp Temi ni iwo se;
f Nko gb’ ohun t’ o dun to yii ri
O mu okan are mi Yo.

3. mp Mo f’ apa iso han mi ,


N’ tori mi l’O jiya;
P A de li ade egun
Lati fi se esin;
Nko m’ ohun t’o O ri l’ara mi
T’o fi jiya po be fun mi.

4. mp Mo joko niwaju Re,


N’nu mole oju Re;
Mo si nfi iyanu nla;
Ranti ibukun Re;
f Ayeraye fere ma to
T’o fi korin iyin Re.

5. B’ akoko ti nkoja lo
N’ isimi pipe de;
f Mo nreti owuro ni
Ti o dara julo,
Gba’ On y’o pe wa sodo Re
B’ iyawo Re lailabawon.
Amin.
692
8.7.8.7.D
Eniti o ba fe Olorun, o fe arakunrin re. 1 Jn. 4:21

1. mf A ra, e je k’ a jumo rin


N ‘ife on alafia;
A ha le ma tun bere pe
O to k’ a ba f’ ija mo
p Ni repo ni irepo,
L’ ayo, ife y’o fi po

2. f B’ a ti nrin lo sile, je k ‘a
Ran ra’ wa lowo lona;
Ota ka wa nibi gbogbo;
mp S’ ona gbogbo l’a dekun,
Ise wa ni, Ise wa ni,
K’ a ma ran ‘ ra wa l’ eru,

3. Nigbat’ ar ‘ ohun Baba se,


T’o ti ji, t’o nfiji,
mp Aras , ko to k’awa k’ o ko
Lati ma f’ ija sile;
K’ a mu kuro , k’ a mu kuro,
Ohun ‘ba mu ‘binu wa.

4. f K’ a omonikeji wa ga,
Ju b’ a ba ti gbe ‘ ra wa;
K’ a fi keta gbogbo sile,
K’ okan wa si kun fun ‘fe;
mf Yio ro wa, yio ro wa,
B’ a wa n’ irepo l’aye.
Amin.
693
S.M
Nkan wonyi ni mo palase fun nyin pe ki eniyan ki o enyin ki o fe omoikeji nyin.Jn.15:17

1. mf ‘F e enikeji re’
Ase Oluwa ni;
O sa f’ ara Re sapere;
Ni fife t’o fe wa.

2. mf ‘Fe enikeji re’


N’ ire tabi n’ ija;
O ko wa pe k’’ a f’ ota wa
K’ a f’ ore san ibi.

3. mf ‘Fe enikeji re’


cr Oluwa nke tantan;
f O ye ko gbogbo wa mura,
K’ a f’ enikeji wa.

4. mf Fe enikeji re’
At’ aladugbo re,
Pelu gbogb’ eni yi o ka,
At’ ota re pelu.

5. K’a f’ enikeji wa
Bi Jesu ti fe wa
Jesu sa fe awon ota Re.
O si sure fun won .
Amin.
694
S.M
E ma ru eru omonikeji nyin.Gal.6:2

1. mf Bukun ni fun ohun,


T’o de wa po n’nu fe;
Idapo awon olufe,
Dabi ijo t’ orun

2. mp Niwaju’ te Baba,
Li awa ngbadura;
Okan n’ireti at’ eru,
Ati ni itunu.

3. p Awa mb’ara wa pin


Ninu wahala wa;
Awa si mb’ ara wa sokun
Ninu ‘ banuje wa.

4. mf Nigbat’ a ba pinya,
Inu wa a baje;
Sibe okan wa y’o j’okan
N’ireti pade.
Amin.
695
C.M
Ife tire ni ki a se , bi ti orun ,beni li aiye, Mat.6:10

1. f Jesu Iye, Oto Ona


Eni ti mo gbagbo,
B’ o ti ko mi , mo ngbadura,
Mo nreti ki nri gba.

2. mf Jeki nma se fe Re laye,


Bi won ti nse l’ orun ,
Awon ti nri O lori te
Ti nsogo n’nu fe Re.

3. Mo ntoro ore –ofe Re


Y’o sin O laifoya;
mf B’ awon angel’ lati tun gba
Adura etan mi.

4. di Danjudaju, em’ elese,


Y’o sin O laifoya;
Mf Okan mi ko lati tun gba
Adura etan mi,

5. Gbat’ O ba s’ ise gbogbo tan,


Emi y’o mo n’nu,
cr Nki o dese l’ohunkohun;
N’tori angel’ ki se.

6. f Emi ki o tun ya O mo,


Nki o si da O mo,
Emi y’o feO laisetan;
N’ tori angel’ ni fe.

7. Un o ma se ife mimo Re
Em’o ma se ife mimo Re
Em’ otso’ elese,
Gba m’ ba fe O tokan –tokan,
Un o ma p’ ofin Re mo

8. Or’ ofe noipa atunse


Li ao fifun mi,
Un o si ma se fe Re
B’ angel ti nse.
Amin.
696
7.7.7.7
Emi ko ri ese lowo okonrin yi. Lk.23:4

1. mf Jesu alail abawon,


O ti f’ eje Re ra mi,
Nko nani ohunkohun,
Lehin agbelebu Re.

2. mf Tire nikan ni mo je,


O fun mi lekun ayo ,
Iyin Re ni un o ma wa.

3. mf Je ki ngbe Itiju Re,


Ki njewo oruko Re;
Ki nwa lati tele O,
P Bi mo tile nri egan

4. f Gbat’ o ba yo n’nu ogo ,


Ti mo de ile l’ oke,
Ahon mi yo kigbe pe
Tire nikan ni mo je.
Amin.

697 L.M
Awa fe e, nitori on tele fe wa.I Jn. 4:19

1. f Awa ko orin ife Re,


Obangiji Oba ogo;
Ko s’ ohun ti lalasi Re,
O ta Re ko si nipekun.

2. f N’nu ife l’o s’ eda aye,


O da eniyan sinu re;
Lati ma s’ akoso gbogbo;
ff Ekorin ‘ yin s’ onibu ore,

3. f Lojojumo l’O si nsike wa;


Beni ko gba nkan lowo wa
ff Korin ‘yin s’ onibu ore;

4. p O ri wa ninu okunkun,
Pe, a ko mo ojubo re;
N’ ife O fi ona han wa;
ff A yin ife Re Olugbala;

5. N’ife O fi Jesu fun wa,


Omobibi Re kansoso ;
P O wa ra wa lowo ese;
ff A yin ‘fe Re Olugbala;

6. Ife Re ran oro Re wa,


Ife Re si mu wa duro;
ff E korin ore –ofe Re,.

7. Gbogbo eda kun fun’ fe Re


Oluwa wa, Oba aye;
ff Gbogbo agbaye, e gbrin,
Orin ife Olorun wa.
Amin.
698
S.M
Nigbati nwon ko si ti nwon o san , tintinu li o dariji awon mejiji.Lk.7:42

1. mf O fun mi l’ edidi,
Gbese nla ti mo je
B’o ti fun mi , O si rerin
P Pe Mase gbagbe Mi.

2. mf O fun mi l’edidi
O san igbese na
B’ o ti fun mi O si rerin
Wipe; ma ranti Mi.

3. mf Un o p’ edidi na mo
B’ igbese tile tan;
O nso ife Eni t’ o san
Igbese na fun mi.

4. f Mo wo mo si rerin
p Mo tun wo mo sokun
mfEri ife Re si mi ni
Un o toju re titi.

5. Ki tun s’ edidi mo,


Sugbon iranti ni
f Pe gbogbo igbese mi ni.
Immanueli sa.
Amin.
699
8.7.8.7.D
Eniti o joko ni ibi ikoko Oga ogo ni yio ma gbe abe ojiji Olodunmare.OD.91l:1

1. mf N’nu ojiji Oga ogo


cr L’ abo mi y’o wa titi;
N’ tori oju Re ti ki sun
f Nso mi n’ gbagbogbo sibe,
f Emi ngbe ninu ojiji
Ti Oba awon oba;
O f’ iye apa Re bo mi,
Nibe ni mo si timi.

2. mf N’nu ojiji Oga ogo


f Mo bo low’ eru gbogbo
N’ tori apa Re gba mi mu,
O si yi mi kakiri.

3. mf N’nu ojiji Oga ogo


f Ibi kan kole de’ be;
Kirist’ n’ ireti, asa , abo,
Olugbala, gbogbo mi.
Amin.

700
7.6.7.6.D.
Oorun fe araiye to be ge, ti o fi Omo bibi re kansoso fun ni.Jn.3:16

1. f Olorun fe araye,
O fe tobee ge,
T’o ran omo Re w’ aye
T’o ku fun elese;
Olorun ti mo tele
P Pe emi ti mo o se si.
O lati ife Re;
Iwo ha fe Mi bi,

2. Loto, Olorun fe mi,


Ani-ani ko si,
Awon t’o yipada si,
Igbala ni won ri;
pp Wo Jesu kristi jiya,
Igi l’’a mo;
Wo eje Re ti o nsan,
Wo ro ma d’ ese mo.

3. p Jesu s’ agbelebu Re,


Un o kan ese mimo;
Labe agbelebu Re,
Un o we ese mi nu;
mf Nigbat’ emi o ri O,
Ni orun rere Re,
ff Nki yio dekun yin O,
F’ ogo at’ ola Re.
Amin.
.
701
8.8.8.D
Ngo fe O Oluwa agbarami.OD.13:1

1. f Un o feran Re, Wo odi mi,


Un o feran Re, Wo ayo mi
Un o feran Re, patapata,
Oiwo nikan, Pelu ‘se Re
cr Un o feran Re, tit’ okan mi.
Y’o fi kun fun ife rere.

2. mf Iwo orun ti a ko da,


Mo s’ ope fun imole Re
Mo s’ ope t’ O seun ota
T’O wo ogbe okan mi san
Mo s’ ope n’tori ohun ninu Re

3. mf Gbe mi ro n’nu re ije yi


Ma je k’ emi tun sako to;
cr Fun ese mi l’ okun , lati
Ma te siwaju l’ ona Re,
ff Wo Oluwa, te mi Alagbara
F’ imole Re te mi lorun.

4. f Un o feran Re, Wo ade mi


Un o feran , Oluwa mi;
di Un o feran Re nigbagbogbo,
L’ ojo ibi, l’ ojo ire,
P Gbati ojo iku, ba de,
f Un o feran Re, titi laelae.
Amin.
702
C.M
Ki kristi ki o le ma gbe inu okan nyin nipa igbagbo .Efe.3:17

1. mf Jesu , kiki ironu Re


Fi ayo kun okan ;
Sugbon k’ a ri O l’ o dun ju.
K’ a simi l’odo Re.

2. Enu ko so, eti ko gbo ,


Ko t’ okan jade ri;
Oko t’o s’ owon t’o dun bi
Ti Jesu Oluwa.

3. p Ireti okan ti nkanu,


Ayo onirele
cr O seun f’ awon ti nwa O
f Awon t’o ri O yo.

4. f Ayo won, enu ko le so


Efa ko le rohin;
Ife Jesu b’ o ti po mo;
Awon Tire l’o mo.

5. f Jesu ‘ Wo ma je ayo wa
Wo sa ni ere wa
Ma je ogo wa nisiyi
Ati titi laelae.
Amin.
703
C.M
Beni Oluwa, Iwo mo pe, mo feran Re. Jn.21:15

1. mf O lugbala mi, ife Re


Ha tobi be si mi.
Wo , mo f’ ife mi, okan mi,
At’ aya mi fun O,

2. Mo fe O nitori toye
Ti mo ri ninu Re;
p Mo fe O nitori iya
T’o kun iyonu.

3. f Bi iwo ti je Olorun
Ti a f’ ogo de lade;
di Iwo ko ko awo eeyan
O f’ ara da iya.

4. p Wo je k’ a bi O l’ eniyan ,
Dsugbon ‘ Wo ko l’ ese;
cr K’ awa rib’ O ti se.

5. f K’ a dabi Re ninbu ife;


L’ ewa ore ofe;
cr B’ at’ ogo de ogo.
Amin.
704
C.M
Oruko kan ti o bori gbogbo oruko .Fili. 2:9

1. mf O ruko kan mbe ti mo fe


Mo fe ma korin Re;
f Iro didun ni l’ eti mi;
Oruko didunni.

2. mf O so ife iyonu Baba,


T’o ku lati ra mi,
O so eje Re ‘ yebiye.

3. cr O so ti iyonu Baba,
Ti O ni s’ Omo Re,
O m’ ara mi ya lati la
Aginju aye ja.

4. f Jesu , oruko ti mo fe,


T’o si dun l’ eti mi;
Ko s’ eni mimo kan l’aye
T’o mo b’ o ti po to.

5. Oruko yi orun didun


L’ ona egun t’ a nrin;
Yio tun ona yangi se
T’o lo s’ od’ Olorun.

6. Nibe pelu awon mimo


Ti won bo nin’ ese,
f Emi o korin titun ni
T’ ife Jesu si mi.
Amin.
705
6.4.6.4.6.6.4.4.
Beni Oluwa; Iwo mo pe , mo fe O. Jn.21:15

1. f Ki nfe O si kristi,
Ki nfe O si;
Gb’ adura ti mo ngba
L’ or’ ekun mi;
p Eyi ni ebe mi;
Ki nfe O si
Ki nfe O si.

2. f L’ ekan ohun aye


Ni mo ntoro;
Nisisyi, Wo nikan
Ni emi nwa;
f Eyi l’ adura mi;
Ki nfe O si kristi,
Ki nfe O si.
Ki nfe O si.

3. p Je ki banuje de
At’ irora;
Didun l’ o jijse Re
At’ ise won.
f Gba won mba mi korin;
Ki nfe O si Kristi.
Ki nfe O si
Ki nfe O si.

4. p Nje , opin emi mi


Y’o jiyin Re,
Eyi y’o je oro
Ikehin mi;
f Adura mi y’o je;
Ki nfe O si Kristi,
ff Ki nfe O si.
Ki nfe O si.
Amin
706
8.8.8D
Oluwa, ko mi ni ilana Re.OD.119:64

1. mf Jesu, ailopin ife Re


Ko si b’ a ti le royin re;
S’ okan ope mi ni Tire,
K’ O si nikan joba nibe;
cr Tire ni mi patapata
Ma mu ‘ fe mi gbona titi.

2. mf Mase je ki ohunkohun
Gba mi l’ okan ju ‘fe Re lo;
K’ ife Re gbe gbogb’ okan mi;
K’ o j ayo; sura ade mil;
Mu fekufe jinna si mi;
K’ ero, ise mi je t’ ife.

3. cr Itansan’ fe fun mi l’ ayo ;


Irora sa niwaju Re
Aniyan, banuje y’ o lo
Nibi tansan wosan Re de;
Jesu , jowo ma je ki nfe
Ohunkohun kan leyin Re.

4. f Je ki nma lepa ife yi


At’ ere giga, lai s’ are;
So ina mimo yi d’ otun
N’ nu emi mi lojojumo;
K’ ajo mi l’osan l’ oru je
Lati so sura owo na.
Amin.
707
C.M
Oluwa ni Oluso- agutan mi, emi ki yio se alaini.OD23:1

1. f Jesu l’ Olus’ agutan mi


Emi ki o salaini;
Nib odo at’ oko tutu
L’o nf’ owo Re to mi.

2. f Bi mo k’ okan mi tun soji


Ni ipa ona nrin nin’ ojiji’ ku
N’ tori oruko Re.

3. p Bi mo nrin nin ojiji ku


mf Emi ki o beru;
Wo mbe pelu mi opa Re
Y’o ma tu mi n’inu

4. mf Iwo te tabili fun mi


Lo j’ awon ota mi;
Iwo d’ ororo sori mi;
Ago mi kun, o nse.

5. f Ire at’ anu Re nto mi


Ni gbogbo aye mi;
Un osi fi ile Olorun
Se bugbe mi laelae.
Amin.
708
D.L.S.M.
Nitori Emi Oluwa Olorun re yo di owootun re mu.Isa.41:13

1. f O nto mi lo , ro ero ‘ bukun,


Oro t’ orun tu mi ninu,
Ohun ti o wu k’’emi se
Sibe Olorun nto mi lo
f O nto mi lo, O nto mi lo
Owo Re l’o fi n to mi lo
L’ otito ni mo fe te l’ E
Nitori O nto mi lo.

2. mp Nigbmiran t’ iponju wa
Nigmiran l’ ogba Eden’
L’ eba odo l’ okun ‘ pju
f Sibe, Olorun nto mi lo.

3. f Oluwa mio d’ owo Re mu


Nko ni kun , nko ni banuje,
F’ ohun y’o wu ti mo le ri
Niwon t’Olorun mi nto mi.

4. Nigba ‘ se mi l’aye ba pin


T’ or –ofe fun mi ni segun
Emi ko ni beru iku
Ni won t’ Olorun mi nto mi.
Amin.
709
S.M
Fi ibukun fun Oluwa, Iwo okan mi ma si se gbagbe gbogbo ore Re.OD.103:2

1. mf F’ ibukun f’ Oluwa
Yin ore- ofe Re
f Gbogbo ohun ti mbe ninu mi
Yin oko Re mimo.

2. mf F’ ibukunf’ Oluwa
Fun opo anu Re.
Mase gbagbe lati dupe
Inu’ re Re si O.

3. cr Loto, O mbaniwi
K’ ise nigbagbogbo,
Lati binu si wa.

4. cr O f’ esere ji O,
O lora emi re,
O wo gbogbo arun re san,
O gba o lowo ku.

5. cr O d’ aso fe bo o
Oro Re gbe o ro,
O so agbara re d’ otun
Bi ti eye idi,

6. f Yin oruko Re nla,


Eni t’ o wo o san,
T’ iseun ‘ fe de o l’ ade,
F’ ibukun f’ Oluwa.
Amin.
710
7.9.7.9.&.Ref.
Fa mi, awa o sare to O O sol.1:4.

1. mf Olugbala mi owon,
Un oma sunmo, sunmo O titi;
Fi eje yebiye Re.
Fa mi rora, mora sunmo, O;
cr Jojumo, gbakugba,
Je ki nmo , gbara Re,
Ki fife t’ Iwo fe mi,
Fa mi mora, mora, sunmo O,

2. N’nu aye ti nkoja yi


di Rora to mi sinu ife Re,
mf Emi ki y’o si sina
Bi Iwo funra re ba nto mi.

3. cr Je ki ntubo feran Re
N’ igba die un o to l’aye;
Ki nfe O titi dopin,
Titi aye ti ko nipekun.
Amin.
711
8.8.6.D
Emi ogbon, ota oye Isa 11”:2

1. cr Emi ogbon, to oju wa


Kuro ninu asan aye,
S’ oto on ‘ fe orun;
Emi oye ti o daju,
Fi imol;e orun fun wa
Lati wa nkan loke.

2. cr Emi ‘ moran’ s’ Amona wa


F’ ijakadi aye ko wa,
K’ a gba ade t’ orun;
mf Emi’ gboya , k’ agbara Re
Ran wa lowo nigba ‘ danwo
Pa wa mo lailese.

3. cr Emi imo to ese wa


Li ona Re ti ko l’ ewu
T’ awon angel’ ti rin;
Nibi t’ Iwo Oluto wa
Mp Iwo Emi ifokansin,
Mu wa sunm’ Olorun.

4. cr Sunmo wa lojo aye wa,


Emi iberu Olorun ,
N’ikoko aya wa;
F’ owo t’ o ye kun nokan wa
Lati sin ife mimo Re,
T’o l’ ododo julo

5. mf Ma to wa lo l’ alafia,
Sinu iye ainipekun.
cr K’ a jere giga na,
K’ a ja ogun aye wa yi
Nipa agbara Re mimo joba .
Amin.
712
8.8.8.D.
Baba mi , Iwo ni ayafe igba ewe mi. Jer.3:4

1. cr Oluwa, n’ igba ewe wa,


A mbe O, s’ Oluto wa;
To wa lo si le rere na;
Pelu’ mole l’ osan l’ oru,
Wa pelu wa l’ ona ajo wa,

2. mp Awa nlo sinu aginju,


Ao le sairi etan Esu;
A ko lokun, ija si le,
Mp Sibe ao segun n’ ipa Re
Titi ao bori ounje orun bo wa.

3. mp Gba’ banuje on wahala


Mu wa sunmo O , Oluwa,
mf Gba ti ayo to yi wa fun ka
Mu k’ okan wa kun fun ope,
cr Gbat irin ajo wa ba Re.

4. mf M’ ese wa duro l’ ona Re,


Ma si jek’ okan wa sako,
Fi suru se amona wa,
Pa wa moi n’nu ewu gbogbo
Bu Iya on aini wa ku,
F’ ese wa mule de opin,.
Amin.
713
8.7.8.7.
Emi mo pe, ninu mi ko si nkan to dara.Rom. 7:18

1. mf Baba orun emi fe wa


N’ iwa mimo l’ododo;
Sugbon ife eran ara
Ntan mi je nigbagbogbo

2. p Alailera emi se
Emi mi at’ ara mi;
Ese’ gbagbogbo ti mo fi sibe;
Wo mi l’ fe at’ ase Re.

3. O fin kan mbe li okan mi


Wo papa l;o fi sibe;
Tori eyi ni mo fi fe;
Tele fe at’ emi si nse;

4. Sibe bi mo fe se rere.
Lojukanna mo sina;
Rere l’ oro Re ma so;
Buburu l’ emi dsi nse;

5. Nigba pupo ni mo njowo


Arsa mi fun idanwo;
Bi a tile nkilo fun mi
Lati gafara f’ ese.

6. Baba orun Iwo nikan


L’o to lati gba mi la;
Olugbala ti o ti ran.
On na ni un o gbamora.
Amin.
714
S.M
E je ki a maa sore fun gbogbo eniyan. Gal.6:10.

1. f Ohun t’ a fi fun O
Tire ni, Oluwa;
Gbogbo ohun ti a si ni;
Owon Re l’o ti wa.

2. mf Je k’a ba ebun Re
Bi iriju rere;
Bi o si ti nbkun wa to;
Be l’a o fi fun O;

3. p Opo ni ise nse;


Ti won ko r’ ounje je
Opo l’o si ti sako lo,
Kuro l’ agbo Jesu.

4. cr K’a ma tu ni ninu,
K’ ama re ni lekun,
K’ a ma bo alainibaba
N’ ise t’ ba ma se.

5. mf K’ a tu onde sile,
K’ a mu asko bo,
Ka ko ni l’ ona Olorun,
B’ iwa kristi l’ ori.

6. cr A gba oro Re gbo


di Busi igbagbo wa,
f Ohun t’ a se fun eni Re ;
Jesu aye fun O.
Amin.
715
C.M
E ma a ru omonikeji yin Gal 6:2

1. mf W o orisun ohun rere,


Awa fe se fe Re,
Ohun wo l’a fi fun O
Oba gbogbo aye/

2. L’ aye yi, wo ni otosi


cr T’o je eniyan Re;
Oruko won n’ Iwo njewo,
Niwaju Baba Re.

3. mp Gba won ba nke n’ inira won


Ohun Re l’ awa bgbo;
Ki o pese fun aini won,
K’O da won l’ ara ya.

4. Lara awon otosi Re.


L’ oju ife Re wal;
Gba si nse itoju won .
A nsesi O , Baba.
Amin.
716
10.10
Nigbagbogbo li enyin sa ni talaka pelu yin.Mk.14:7

1. mf Mo nlo , talaka mi mbe l’ odo yin


E le ma s’ ore fun won b’e ti nfe,

2. mf Eyi ni ogun t’ Olugbala wa


K’a sile f’ awon Tire k’o to lo.

3. Wura on jufu ko , otosi ni;


K’a ma ran won lowo nitori Re,

4. cr Eru nla ko, ogun t’o l’oro ni;


Ti nf’ ilopo’ bukun f’ eni ntore.

5. mp Tiwa ki se na bi? L’ ojude wa


Ko ni takala at’ asegbe wa?

6. Ohun irora awon t’iya nje


Ko ha nke si wa lati f’ anu han?

7. Okan t’ogb’ ogbe, okan ti nsise,


Ekun opo,at’ alaini baba
8. cr On t’ O f’ ara Re fun wa, si ti fi
Eti orun f’ awa iranse Re.

9. Ko s’ otosi kan ti ko le sajo


F’ eni tosi ju lo, agbara ni.

10. Isin mimo ailabawon l’eyi,


Ti Baba mbere’ owogbogbo wa.
Amin.
717
11.11.11.11.
On le pa ohun ti mo fi le lowo mo 11:Tim.1:12

mf Jesu , emi o fi okan mi fun O


mp Mo jebi mo gbe. Sugbon Wole gba mi.
. cr L’ aye ati lorun ko s’eni bi Re.
P Iwo ku f’ elese f’ emi na pelu

2. mf Jesu , mo le simi le oruko Re


Ti angeli wa so, lojo ibi Re
P Eyi t’ a ko t’ o han lor’ agbelebu.
cr Ti elese si ka , won si teriba.

3. mf Jesu, emi ko le sai gbekele O


Ise Re l’ aye kun f’ anu at’ ife.
mp Elese yi O ka, adete ri O.
Ko s’ eni buruju, ti Wo ko le gba.

4. mf Jesu, mo le gbekele mi le oro Re


Bi nko tile gbo ohun sanu Re ri.
Gbat’ Emi Re nko ni, o ti dun po to.
di Ki nsa fi barale k’ eko lese Re.

5. f Jesu toto- mo gbeekele le o.


enikeni T’ o wa,, wo ki o tu nu,
ff oto ni leri Re, owon leje Re
Wonyi ni gbala mi, Wo l’ Olorun mi.
Amin.
718
8.8.8.9.D
Gbe agbelebu re ki o si ma to mi lehin.Mat.16:24

1. cr Mo gbo Olugbala mi npe.


Mo gbo Olugbala mi npe;
Mo gbo Olugbala mi npe,
Gb’ agbelebu re si te le mi.
ff Ona t’ O la l’ emi o rin
Ona t’ O la l’ emi o rin.
Ona t’O la l’emi o rin
Em’ o tele, tele titi lae.

2. mf Em’ o ba koja ogba ni.


Em’ o ba koja ogba ni.
Em’ o ba koja ogba ni
Em’ o tele, tele titi lae.

3. mf Em’ o ba koja idajo


Em’ o ba koja idajo
Em’ o ba koja idajo
Em’o tele, tele titi lae.

4. ff Y’o fun mi l’ore at’ ogo


Y’o fun mi l’ore at’ogo
Y’o fun mi l’ore at ogo
Y’o je t’ emi t’ emi titi lae
Amin.
719
L.M
Ongbe Olorun ngbe okan mi.OD.42:2

1. mp O lorun mi, Wo l’ emi mi.


Ki imole oro t’ o la;
F’ agbara Re han l’ okan mi,
Ki O si mu mi l’ ara ya.

2. di Ongbe Re l’ ongbe okan mi.


N’ ile aginju gbigbe yi
Ebi npa mi mo si daku.
cr Fe Re nkan lo le yo mi.

3. Iwo nikan l’ okan mi nfe


N’ ile gbigbe yi Olorun;
Mo fe ni ore-ofe Re
Ju gbogbo oro aye lo.

4. mf Ife t’o sowon julo


Y’o kun okan at’ ahon mi,
Ogo, ayo alafia mi
Y’o je lati so iyin Re.

5. Gbogbo aye mi un o ma
F’ orin ope’ bukun fun O;
Iyin t’o ye oruko Re
Ni un o gbe s’ oke si O.

6. Oruko Re wa l’ enu mi
At’ ero mi lor’ eni mi;
Mo nse asaro ise Re.
Pelu ‘wariri l’ oganjo,

7. Mo mi owo Re n’ nu se mi;
Nje un o korin titobi Re
Olorun , wo t’o mu mi yo
Labe ojiji iye Re.

8. f Mo sun mo O timo timo ;


Agbara Re y’o si gba mi
Low’aye y’o orun ebe
Igbala Re ki tase lae.
Amin.
720.
8.7.8.7.&Ref
Se alabapin pelu mi ninu iponju bi omo –ogun rere Jesu kristi,11:Tim2:3

1. f E dide, Omo Igbala,


Eyin t’ efe Oluwa,
Dide, ilu alagbara
Ki ota to de Sion.
f F’ agbara re korin kikan
Bi iro omi okun,
Nipa eje kristi Jesu
Awa ju asegun lo,
Awa ju asegun lo,
Awa ju asegun lo,
Nipa eje kristi Jesu,
Awa ju asegun lo,

2. cr Egbe mimo ti gbani


Ti won ti nrin ona yi;
mf W’ asia won t’o nfe lele,
A segun nipa kristi.

3. f A ti gbe ku mi ni’ segun,


Iye wa mbe n’ nu kristi;
L’ ojo’ farahan Oluwa
Ao ho ihop ayo

4. f Lajipe ao de’ bi ite Re,


Ao si mo Oba ogo;
Nibe ao ke’kabiyesi’
Gbogbo wa y’o gba ere.
Amin.
721.
11.11.11.11.&.Ref.
So fun awon omo Israeli ki won ki o te siwaju Eks.14:15

1. mf E ma te siwaju, Keistian ologun


Ma tejumo Jesu t’O mbe niwaju;
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
Wo Asia Re wa niwaju ogun,
ff E ma te siwaju, Kristian ologun
Sa tejumo Jesut’O mbe niwaju

2. f Ni Oruko Jesu, ogun esu sa,


Nje kristian ologun ma nso si segun;
cr Otun apadi mi ni hiho iyin,
Ara, gb’ojun yin ga, gb’orin yin soke

3. f Bi egbe ogun nla n’Ijo Olorun ,


di A ra n’rin l’ ona awon mimo nrin;
mf A ko ya wa ni pa , egbe kan ni wa,
Okan ni reti, ati eko , ni ife.

4. Ite ijoba wonyi le parun,


Sugbon Ijo Jesu y’o wa titi lae,
cr A n ileri kristieyi ko le ye.

5. f E ma mi kalo, eyin eniyan ,


D’ ohun yin po mo wa l’ orin isegun;
cr Ogo , iyin ola fun kristi Oba;
Eyi y’o ma je orin wa titi.
Amin.
722
11.11.11.11.&.Ref.
Iwo ti fo opagun fun awon ti o beru Re.OD.60:4

1. f Di dan l’ opagun wa, O nto ka s’ orun;


On f’ ona han ogun si ile t’ orun;
B’a ti nlo laginju l’a nf’ayo gbadua,
Pe l’ okanisokan l’a m’ on orun pon,
Didan l’ opagun ogun si ile t’ orun.

2. mf Jesu Oluwa, l’ ese mimo Re


Pelu okan ayo l’omo Re pade,
cr A ti O sile, a ti sako,
To wa Olugbala, si ona toro

3. mf Jesu apere wa, Wo s’ omode ri.


Se wa l’omo rere, k’a n’iwa pele,
cr Li akoko ewu , nibo l’a ba re
B’o ye li odo Re v, Olugbala wa.

4. f To wa l’ojo gbogbo l’ona awa nto,


Mu wa nso s’ isegun l’ori ota wa.
di K’angeli Re asa wa ‘ gb’oj orun su
p Dariji, si gba wa l’akoko iku.

5. f A ba le pe l’awon angeli l’oke


Lati jumo ma yin n’ite ife Re;
cr Gbat’ ajo wa ba pin ailopin.
Amin.
723.
8.58.5.&.Ref.
Sugbon eyi ti eniyan ni, e di imu sinsin titi Emi o fi de.1fi2:25

1. f Ha egbe mi e wa asia
Bi ti nfe lele
Ogun Jesu fere de na,
A fere segun.
ff D’ odi mu Emi fere de’
Beni dahun nwi,
Ran dahun pada s’ orun pe
Awa o di mu.

2. f Wo opo ogun ti mbo wa;


Esu nko won bo;
Awon alagbara nsubu,
P A fe damu tan.

3. f Wo asia Jesu ti nfe,


Gbo ohun ipe;
A o sehun gbogbo ota
Ni oruko Re.

4. f Ogun ngbona girigiri,


Iranwo wa mbo;
Balogun wa mbo wa tete.
Egbe tujuka.
Amin.
724
7.6.7.6.D
Nitorina, egbe gbogbo ihamora Olorun wo.Efe6:13

1. f Duro, duro fun Jesu,


Eyin om’ ogun krist’
Gbe asia Re s’ oke
A ko gbodo fe ‘ segun
cr Lai isegun de segun
Ni y’o ogun Re;
Tit’ao segun gbogb’ ota
Ti krist’ y’o jOluwa.

2. f Duro, duro fun Jesu,


F’ eti s’ ohun ipe
Jade lo s’ oju ija
Loni ojo nla Re;
Eyin akin ti nja Re;
Larin ainije ota,
N’nu ewu e.ni’ gboya,
E ko ju ja s’ ota

3. p Duro, duro fun Jesu,


Duro l’ agbara Re;
P Ipa eniyan ko to,
Ma gbekele tire,
cr Di hamora hinrere,
Ma s’ ona .ma gbadua.
B’ise tab’ ewu ba pe,
Ma se alai de ‘ be.

4. f Duro, duro fun Jesu,


di Ija na ki y’o pe;
p Oni ariwo ogun,
f Ola, orin segun
ff Eni t’o ba si segun
Y’o gba iye
Y’o ma ba Oba ogo
Joba titi laelae
Amin.
725
S.M
E je alagbara ninu Oluwa , ati ninuagbara ipa Re.Efe.6:10

1. f O m’ ogun krist’ dide,


Mu hamora yin wo
Lo ipa t’ Olorun fun yim.

2. cr Gbe’ pa Olorun wo
T’ Oluwa om’ ogun,
mp Eni t’o gbekele Jesu,
O ju asegun lo.

3. mf Ninu ipa Re nla,


O ni ki E duro,
Tori k’e ba le jija na,
E di hamora yin.

4. cr Lo lat’ ipa de ‘ pa
Ma ja, ma gbadura;
Te agbara okunkun ba,
E ja k’e si segun.

5. Leyin ohun gbogbo,


Leyin gbogbo ija,
K’ e le segun n’ ipa kristi
K’e si duro sinsin,.
Amin.

726 C.M
Awon ogun orun si nto O lehin.1fi19:14

1. f O mo Olorun nlo s’ ogun,


Lati gb’ade Oba;
Opagun Re si nfe lele,
Ta lo s’ om’ ogun Re.

2. mp Eni t’o le mu ago na,


T’o le bori ‘ rora,
cr T’o le gbe agbelebu Re;
f On ni om’ ogun Re;

3. mf Ajeriku ti o nko ku,


T’or orun si sile;
T’o ri Oluwa Re loke,
T’o pe k’ O gba on la.

4. di Pelu idariji l’ enu


Ninu ‘ rora iku.
cr O bebef’ awon t’o np’ a lo,
f Tani le se bi Re.

5. ff Egbe mimo , awon wonni;


T’ Emi mimo ba le.
Awon akorin mejila;
Ti ko iku si.

6. f Won f’ ayaran ida ota,


Won ha eranko ja.
di Won f’ orun won tele fun ‘ku
Tani le se bi won.

7. ff Egbe ogun f’ agba t’ ewe.


L’okunrin l’obinrin
Won y’ ite Olugbala ka.
Won wo aso funfun.

8. f Won de oke orun giga,


di N’nu ewu ponju;
p Olorun fun wa l’agbara
Ki a le se bi won .
Amin.
727
C.M
Ma a ija rere ti igbagboi.1Tim.6:12

1. mf A jagun Jesu l’emi bi.


At’omoehin Re;
Un o ha beru lati wasu
Agbara isin Re.

2. mf Ao ha gbe mi soke orun


lori busun rorun.
Gbati opo ja’ere na
Lori okun eje.

3. Ko ha s’ ota lati ba ja.


Un o ha ko ‘gbi lile
Aye ha fe ore-ofe
T’y’omu mi odo Re.

4. p Mo ni ja, bi un o ba joba.
P Ran ‘gboya mi lowo ;
Un of’ ara da gbogbo ise
Pelu iranwo Re.
Amin.
728
S.M
E ma soro ki e si ma gbadura.Mk.14:38

1. mf Ma so ‘ra okan mi.


Awon ota dide;
di Ogun ese si mura tan.
Lati fa o lu’ le

2. mf Ma ja ‘na gbadura,
Ma so reti mu.
Bere l’ Otun l’ojojumo.
Tor’ agbara loke.

3. mf Ma ro p’o ti segun.
Ma si se tu’ ra’le
Ise re ki o pin titi.
Iwo o fi gb’ ade.

4. mf Ma ja lo okan ni ,
Tit’ iku y’o ti de;
Olorun y’o mu o lo’ le.
Gb’ emi re ba piny.
Amin.
729
9.6.9.6.& Ref
Sugbon awon ti o ba duro de Oluwa yio un agbara won se.Isa 40:31.

1. mf E yin Olukore nin’ oko


T’ are fere mu tan.
cr E roju duro de Oluwa,
Y’o s’agbara d’ Otun .
mf Awon t’o duro d’ Oluwa.
Y’o s’ agbara won d’ otun.
f Won o fi iye fo,
Won o fi iye fo bi idi,
Won o sa, ki y’o kare
Won o rin , ki y’o re won.
Won o sa , won ki y’o kare
Won o rin, ki y’o re won
Won o sa , won ki y’o kare
Y’o lin., kiy’o re won.

2. p Nigba are ati rewesi,


A ngb’ okan wa si O;
mf Leyin t’a Olugbala gbo,
Ki l’abo ao tun beru.

3. f E yo Omba wa gbe l’ ojojo


Ani titi d’ opi;
Woke e si ma tesiqaj,
Y’o fun nyin l’ agbara.
Amin.
730
C.M
Tireli emi, gba mi.OD.119:94

1. mf Tire titi lae awa se


Oluwa wa Orun
cr K’ ohun at’ okan wa wipe;
Amin, beni k’o ri.

2. mf Gbati aye ba ndun mo ni,


T’o si nfa okan wa;
P K’iro yi pe Tire ;’awa’
Le ma dun l’ eti wa.

3. mp Gbat’ ese pelu etan re


Ba fe se wa n’ibi;
P K’ iro yi pe ‘ Tire l’ awa’
Tu etan ese ka.

4. mf Gbati esu ba ntafa re


S’ ori ailera wa;
f K’ iro yi pe ‘ Tire l’awa’
Ma je ki o re wa.

5. mf Tire,n’igb’a wa l’omode
cr Tire, n’igb’a ndagba
di Tire, n’igb’a ba ndarugbo
p Ti aye wa mbuse.

6. ff Tire, titi lae l’awa se;


Af’ ara wa fun O;
Titi aye ainipekun,
Amin, beni k’ ori
Amin.
731
C.M
Emi nlepa lati de oiupn ire-ije ni fun ere ipe giga Olorun.Fill3:14

1. f Ji, okan mi dide giri,


Ma lepa nso kikan;
F’ itara sure ije yi,
P Fun ade ti ki sa.

2. mf Awosanma t’o yi wa ka,


Ni eleri se re;
cr Gbagbe irin at’ eyin wa,
Sa ma tesiwaju .

3. f Olorun nf’ ohun Isoji


Ke si o lat’ oke;
Tika Re l’ O npin ere na,
F’ oju t’o ns’ aferi .

4. mf Olugbala Wo l’ omu mi
Bere re’ je mi yi;
Nigbat’ a ba de mi l’ade,
Un o wole l’ ese Re.
Amin.
732
8.7.8.7.D
Sugbon ohunkohun ti o jasi ere fun mi, awon ni mo ti kasi ofo nitori kristi.Fill.3:7

1. Jesu mo gb’ agbelebu mi


Ki nle ma to O leyin;
Otosi at’ eni egan,
Wo l’ohun gbogbo fun mi
Bi ini mi gbogbo segbe
Ti ero mi gbogbopin
Sibe, Oloro ni mo je;
T’ emi ni krist’ at’ orun.

2. Eda le ma wahala mi,


Y’o mumi sunmo O ni;
Idanwo o mu simi
Orun o mu’simi wa,
Ibanuje ko le se nkan
Bi ‘ fe ba wa fun mi;
Ayo ko si le dun mo mi
B’iwo ko si ninu re.

3. Okan mi, gba igbala re;


Bori ese at’ eru;
F’ayo wa ni ipkipo,
Ma sise lo, ma weyin ,
Ro t’emi t’o wa ninu Re
At’ ife Baba si O
W’ Olugbala t’ O ku fun O,
Omo orun mase kun.

4. Nje koja lat’ ore s’ogo


N’nu adura on ‘gbagbo;
Ojo ailopin wa fun O
Baba y’o mu o de’ be
Ise re l’;aye fere pin
Ojo ajo re nbuse
Ireti y’o pada ‘ sayo,
Adura s’ orin
Amin.
733
10.9.10.9..&.Ref.
E fi ayo sin Oluwa,OD.1002

1. f Pelu ayo l’aso sise f’ Oluwa


Pelu ife l’ao f’ owo wa se
Isekise ti o ba yan fun wa
L’ododo l’ ao sise ‘ranse wa,
cr Sise fun Jesu.
L’ayo l’ao lo ;l’ayo l’ao lo;
Sise fun Jesu,
Ninu ogba Re laye.

2. f Pelu adun li ao so itan na


T’ ife nla re s’awa eniyan,
Kristi itansan ogo ti Baba,
L’ofe l’on ofi’bukun fun wa.

3. p Pelu ‘rele l’ao so itan na;


Ao fi otito rin l’ona Re;
Ao to asako s’od’Olugbala,
Ao f’Odagutan han elese.
Amin.
734
8.7.8.7.&.Ref.
Omo, lo sise loni ninu ogba ajara mi.Mat.21:28

1. mf Gbo bi Oluwa ti mbebe,


Ise wa fun gbogbo wa;
cr Gbo bi Emi ti nwi pelu,
Je ipe na bayi pe;
f Mo setan lati sise fun O Jesu,
Emi de ‘ ran mi;
cr Mo nfe lati se ife Re ni pipe,
Un o lo s’ ibit’ O baran mi
Mo setan lati sise fun O Jesu
Emi de,ran mi;
Mo se tan fun ise Jesu.

2. cr Ohun kan npe o nisiyi,


Fi eti ohun na;
mp O nso si o l’eti jeje,
Je ipe bayi pe.

3. di Okan pupo nku n’nu ese,


Yara lati se ‘ranwo;
Tori akoko nkoja lo;
So fun Jesu bayi pe.
Amin.
735
7.7.7.7.
Ki enyin ko fi ara nyin fun Olorun li ebo aaye mimo, itewogba, Rom.12:1

1. mf Gbe aye mi, Oluwa,


Mo ya si mimo fun O
Gba gbogbo akoko mi,
Ki won kun fun iyin Re.

2. f Gba owo mi, k;’o si je


Ki nma lo fun ife Re,
Gba ese mik’o si je
Ki won ma sare fun O.

3. Gba ohun mi , je ki nma


Korin f’ Oba mi titi;
Gbe ete mi, je ki won
Ma jise fun O titi.

4. mf Gba wura, fadaka mi.


Okan nki o da duro;
Gba ogbon mi ko si lo
Gege bi O ti fe .

5. mp Gba ‘fe mi fi se Tire,


Ki o tun je t’ emi mo;
Gb’okan mi, Tire n’ise,
cr Ma gunwa nibe titi.

6. f Gba’ feran mi Oluwa


Mo fi gbogbo re fun O;
Gb’emi papa, lat’oni
Ki m’je Tire titi lae.
Amin.
736
7.6.7.3.7.7.7.3.
Emi ngbagbe awon nkan ti o wa lehin,mo si n noga wo awon nkan ti o wa niwaju
.Fill.3:13.

1. f Gbekele Olorun re
p K’o ma nso K’o ma nso
D’ileri Re mu sinsin,
K’o ma nso
mase se oruko Re,
B’o tile mu egan wa,
Ma tan ihin Re kale,

2. f O ti pe o s’ ise Re
cr Sa ma nso sa ma nso
p Oru mbo wa , mura sin
Sa ma nso
Sin ife at’ igbagbo;
f Gbekele agbara Re,
f Fi ori ti de opin,
Sa ma nso,

3. f O si fun Oni ‘rugbin?


Sa ma nso Sa ma tun kore,
Ma ma nso;
Ma sora ,si ma reti
Sa ma nso.

4. p O ti wipe opin mbo?


cr Sa ma nso ma nso.
Kristi l’atilehin re,
On na si ni ounje re,
Y’o sin o de nu ogo ,

5. K’a ri okan Re n’nu ,


K’ife Re je ayo re,
L’ojo aye re gbogbo,
Si ma nso.
Amin.
737
7.6.7.5.D or 13:12:13.12.
Oru mbo wa nigbati enikan ki o le sise.Jn9:4

1. f Sise tori oru mbo siseli owuro;


Sise nigbat’ iri nse; sise n’nu tanna;
Sise ki osan t’o pon, sise nigb’ orun nran;

2. f Sise tori ,no ; sise l’osan ganggan;


F’akoko rere fun igba ni nkan lati npamo;
F’ Olukukulu igba ni nkan lati pamo.
Sise ‘tori oru mbo gba se o pari

3 f Sise ‘tori oru mbo ; sise l’ oju ale


Sise ‘gbat’imole wa, ojo bu lo tan;
Sise titi de opin ,Sise titi d’ale
Sise ‘gbat’ ile ba nsu, gba ‘ se o pari.
Amin.
738
12.12.12.&.Ref
Awon o duro sisin ni ninu iranse na.Ise A 6:4.

1. f Ao sise Ao sise Omo’ Olorun ni wa,


Je k’atele ipa ti Oluwa wa to,
mp K’afi moran Re so agbara wa dotun,
cr K’a fi gbogbo okun wa sise t’a o se .
f Foriti; Foriti.
Ma reti. Ma sona,
Titi Oluwa o fi de.

2. mf Ao sise Ao sise awon t’ ebi npa,


Ko awon alare lo s’orisun iye;
Ninu agbelebu l’awa o ma sogo,
Gbati a ba nkede pe; O fe ni igbala’

3. f Ao sise ao sise gbogbo wa ni y’o se.


Ijoba okunkun at’isina y’o fo;
Ao si gbe oruko Jehota l’eke,
N’nu orin iyin wa pe ‘Ofe n’igbala’

4. f Ao sise ao lagbara Oluwa,


Agbada at’ ade y’o si je ere Wa;
Gbat’ ile awon Oloto badi ti wa,
ff Gbogbo wa o jo ho pe; Ofe n’igbala.
Amin.
739
4.10.10.4.
Lo sise loni ninu ogba ajara mi.Mat.21:28

1. f W a ,ma sise,
f Tani gbodo s’ ole ninu oko
Gbati gbogbo eniyan nkore jo,
Kaluku ni Baba pe fun ise’

2. Wwa,ma sise,
Gba pe giga ti angeli ko ni
Mu hinrere to t’agba t’ewe lo,
di Ra , gba pada, wawa l’ akoko nlo,

3. mf Wa, ma sise,
Oko po, alagbase ko si to,
cr Aye titun po fun wa lati kun,
Ohun ona jinjin , at’ itosi
Nkigbe pe; Wa’

4. f Wa, ma sise
Le yemeji on aigbagbo jina,
K’o alailera ti ko le se nkan,
di Ailera l’ Olorun a ma lo ju
Fun ‘se nla Re.

5. cr Wa, ma sise,
Simi ko si nigbat’ ise osan,
Titi orun yio fi wo l’ale ,
f Ti awa o si gbo ohun ni pe;
O seun Omo.’

6. Wa, ma sise ,
Lala na dun ere re si daju .
cr Ayo won, simi won y’o ti po to
p Lod’’ Oluwa’
Amin.
740
C.M
A npa wada si aworan kanna, lati ogo de ogo.11Kor.3:18

1. mf Jesu mase je k’a simi.


Ti o fi d’ okan wa;
T’o fun ni ‘bale aya,
T’o wo ite ese.

2. p A ba le wo agbelebu,
Y’o si ohun aye d’ofo,
t’yo mu ‘banuje tan.

3. f Titi okan wa yo goke,


T’ao bo lowo ara;
T’ao fi r’alafia pipe,
Ati ayo orun.

4. f Bi a si ti ntejumo O,
K’a d’okan pelu Re;
K’a si ripipe ewa Re
Ati ayo orun .

4. f Bi a si ntejumo O
K’a d’okan pelu Re.
K’a si ripipe ewa Re
N’ile ayo l’oke.
Amin.
741
L.M
E fi ayo sin Oluwa .OD.100:2

1. mf Ki l’awa y’o fun Olorun


Fun gbogbo ore Re si wa
f Ao f’ ayo ranti oko Re,
Ao si fi iyin Re han.

2. mf Iwo lui olu ife wa.


L’odo Re l’anr’ohun gbogbo
Si orisun lat’ oke wa
Je k’o san si okan gbogbo.

3. Be l’ao kede agbara Re


At’ or-ofe Re felese;
Titi gbogb’ eda y’o mo O
Ti won o si tewo si O.

4. mp Silekun sile fun ‘se Re.


T’aye at’ esu ki o le si.
Je k’oro Re ma gbe nu wa
Ki eso na k’o wa titi.

5. Bukun eso afunrugbin


k’a le ma so eso titi;
K’a tan hinrere Re k’aye
Ati otiotoRe titi.

6. mf Ao ma tioto ipa Re
Gbat’a ba se wa pe n’ife;
Bi owon n’ile Olorun ,
L’ao duro , t’oao ni jade mo.
Amin.
742
8.8.8.d.
E ma ni gbona okan , e ma sin Oluwa. Rom.12:11

1. mf iJesu inu wa ti dun to,


Pe a o je omo eyin Re;
Awa t’a nf’aye wa
Gbo t’Olorun ati t’eda,
Anf’osan se ise rere
Anf’ oru gbadura.

2. `cr A ko r’aye fun iroju


Tabi fun imele sise;
Awa nte siwaju ;
Are ara ko si rara,
F’eni ti o nsin Olorun
T’o mo lowo nikan.

3. mf T’ojo t’ erun l’onyara lo,


Akoko na koto fun wa
Lati korin ‘yin Re
Wakati ayo na ko to ,
A fe dapo m’ogun orun
Korin ayeraye.

4. mf Awa nfe lati ma yin o


cr Pelu awon ogun yin O,
f Awon egbe didan
di Ti nke Mimo, Mimo, Mimo
f K’a ma korin y’ite Re ka
ff Orin ayeraye.
Amin.
743
8.8.8.D
Ni Ise Sise e ma se Ole. Rom 12:11

1. mf Awon ti nf’ ise won fale


Won nfi t’ Oluwa jafara;
Awon mo ise on se ‘biju
Ko mo ise on igbagbo ;
Won ya ‘hun t’Olorun so po
Aapon ati ifokansin.

2. mf A f’ idi ise wa mule


T’a nse pelu ‘tara emi,
Olorun to da gbogb’ ojo,
Ni k’a simi l’ojo keje ;
Ba ti nf’ ise ra ‘gba pada
Dun mo Oluwa ti a sin.

3. Ao ma yo bi Olorun
Fun wa n’ise on itara;
cr N’tori ise ti on f’ase si
f Y’o ebo eni fun ogo Re
B’awon eni mimo l’oke
B’a ti njosin ife npo si.
Amin.
744
8.6.8.6.8.6.
Baba mi nsise titi di nisisiyi, emi si nsise.Jn.5:17

1. mp Jesu ma yo mi n’nu se Re.


To mi fun ife Re.
N’tor’emi ko le sairise
L’oko tiobi yi.
Emi ko ni bere oya
Ki nsa sin O si.

2. mp Opo li awon ti nsin O


Aye wa f’ opo si.
Ise itoju ajara
L’O yan f’ won miran;
Awon akoni mbe l’ ogun
Omode mbe n’ile.

3. Gbogbo ise li o dara,


B’o ba sa ti wu O;
Bi osise nf’ ife josin.
Ise re y’o wu O;
Wo ki o sai bukun ise
At’ osise pelu.

4. Jesu ti se iru ise;


T’o on k’ase loni
Emi ba ni pin n’nu se Re
Y’o ba jogun pelu
Un o sise ki nle j’omo Re.
di Jowo mase yo mi.
Amin.
745
8.7.8.7.d
E ya Barnaba on saulu soto fun mi fun ise ti mo ti pe won si Ise.A.13:2

1. mf Gbo ohun Jesu ti nke pe;


Tani y’o sise loni;
Oko pon pupo fun kore?
Tani y’o lo ko wale?
cr Kikankian l’Oluwa npe,
Ebun nla ni y’O funO,
Tani y’ofi ayo dahun
f Pe ‘ Emi ni yi, Ran mi?

2. mf B’iwo ko le la okun lo.


Lati awon keferi;
O le ri won nitosi re;
Nwon wa l’enu ona re.
B’oko le fi wura tore
Ebun miran ko kere,
Die t’o si se fun Jesu,
Yebiye ni l’oju Re

3. mp B’Iwo ko le se alore
L’ori odi Sioni
Lati k’oka s’ona orun ;
P Lati f’ iye lo eda
Wo le f’adura at’ ore
Wo le se gegebi Aaron
T’o gb’ owo woli soke.

4. mf Ma je k’agbo ki o wipe,
Ko si nkan t’emi le se’
Nigbat’ emi eniyan nku
Ti Oluwa si npe O,
F’ayo gba ise t’O ran O,
F’ ise Re se ayo re
ff Gbat’ o npe o, tara dahun
Pe; emi ni yi, ran mi.
Amin.
746
8.7.8.7.&.Ref
Wo o awa ti fi gbogbo re sile awa si nto O lehin Mat.19:27

1. mf Mo fi gbogbo re fun Jesu


Patapata, laiku’ kan
Un o ma fe, un o si gbekele,
Un o wa l’odo Re titi.
f Mo fi gbogbo re,
Mo fi gbogbo re,
Fun O, Olugbala mi, ni
Mo fi won sile.

2. Mo fi gbogbo re fun Jesu.


mp Mo fi rele wole fun ;
Mo fi ‘gbadun aye sile,
cr Gba mi, Jesu si gba mi ,

3. Mo fi gbogbo re fun Jesu,


Se mi ni Tire nikan ;
cr Je ki nkun fun Emi Mimo,
Ki nmo pe, Wo je t’emi.

4. Mo fi gbogbo re fun Jesu,


Mo fi ara mi fun O,
Fi fe at’agbara kun moi;
Ki’ bukun Re ba le mi,

5. Mo fi gbogbo re fun Jesu,


Mo mo p’Emi ba le mi;
P A ayo igbala kikun ;
Ogo, ogo f’ oko Re.
Amin.
747
L.M
E ma ronu awon nkan ti mbe loke,ki ise awon nkan ti mbe li aiye;kol.3:2

1. mf Olugbala josokale
F’or-ofe Re ran mim lowo;
Yo ife aye l’okan mi.
Pese aye fun ara Re.

2. Fi ara Re kun emi mi.


Ki O si so mi d’omiran
Ko fe le pa ohun miran
Bikos’ Wo losan l’oru.

3. Niwon ‘gbati mo wa l’aye


Nki o lepa ire miran ;
Emi y’o dagbere f’ aye
Pelu gbogbo itanje re,

4. Ona t’Olugbala mi rin.


Ni un of’iyara wa kiri;
Beeli ki o si mo
Ife miran leyin Tire.

5. f Lat’ oni lo ‘ k’adun aye


Ma ri ibi gba l’okan mi;
Se ni Tire, eto ni ,
Iwo n’ise Oluwa re.

6. cr Iwo ola afe asan


Ti aye yi le fifun ni.;
Okan mi kogbogb’ etan yin
Kristi nikan ni y’o ma sin.

7. f Iwo nikan ni mo le fe
Pelu ife atinu wa;
Ayo wo l’o tobui to yi
Pe, iwo gba mi mni Tire

8. Ko s’ ohun ti mo fe l’aye
Ju k’ife Re wa l’aya mi;
Eyiyi sa ni mo ntoro,
Mo ko ohun gbogbo ‘ yoku
Amin.
748
L.M
Nje nisisiyi , Oluwa , kini mo duro de’ Ireti mimbe li odo Re OD.39:7

1 mf Kili ohun ti mo nlepa?


Kini reti at’ ife mi ?
Ki ntele odagutan na
Ki nma lepa aworan Re.

2. Gbogbo ‘reti mimbe n’nu Re,


Pe ki ntun je eni t’o fe ;
cr Ki nri igbala Re laye
Ki nsi je adun Re l’oke.

3. di Mo npongbe f’ Oluwa iye


mp To ku l’oke kalfari;
F’orisun omi. On eje
Ti nti ha Imanuel jade.

4. cr Mo npongbe f’ omi ife Re.


Emi ayo ti a ko mo,
Ki emi si fun mu l’oke
P B’o ti nsun , mu l’at’ ori ite.
Amin.
749
7.6.7.6.D.
Ki eyin ki o fi ara nyin fun Olorun li eb aaye Rom.12:1

1. mf Emi ,okan at’ ara;


Jesu mo fi fun O;
Fun ebo mimo lati
Ma je Tire titi,
cr Mo fi ara mi rubo ,
Jesu Tire l’emi,
Ki gbagbo mi mse ye
di Se mi n’ tire nikan .

2. mf Jesu ,Olugbala nla.


Mo gbekelemi le O.
Mo wa igbala nla Re.
Mo bere ‘leri Re.
di Mo gba eya ara mi.
Kuro labees;
Mo fi fun b’ ohun elo.
Lati lo si segun.

3. mp Mo f’ ise t’ ara sile


Ki nle wa lodo Re.
Jesu Olugbala mi.
f F’ emi Re sinu mi.
Tire li emi, Jesu
T’a f’ eje Re we mi.
Ebo fun Olorun .
Amin.
750
6.5.6.5.D.&Ref.
Nigbana li emi wipe , Emi niyi;ran mi .Isa 6.8

1. mp Gbe ewa Re wo mi
Bi mo lti njosin,
cr Mo jowo ara mi.
Fun O Oluwa
Fi ewu ogo Re.
Se oso fun mi.
mf Ki nle di asegun
Ni gbogb’ aye mi.
Emi pelu Jesu,
Idapo didun;
cr Okan ti Jesu njoba
L’od’ominra.

2. mp Fun mi iran na.


Ti o ngoke lo
Si ibi ite Re.
Ki nye s’aniyan,
mf Ohun gbogbo y’o si
Sise fun ire;
Gbogb’ohun t’o diju
Y’o ye mi gbangba.

3. cr Nibi agbelebu
Jo , fa mi mora,
Ki nmo agbara Re;
F’ ese mi mule,
Wa ,we mi mo laulau,
M’abawon kuro;
Ese nso mi d’eru,
So mi d’omnira.

4. p Fun mil’okan mimo


At’ inu funfun;
Ni nsa le ma segun
Ni gbogb’ aye mi;
B’ ogun tile gbona,
T’ija na si le,
f Pelu Re , Asegun,
Isegun daju.
Amin
751
L.M
Oun yoo fi Emi mimo ati ina baptisi nyin.Lk.3:16

1. Iwo t’o t’oke sokale


Lati f’ ina orun fun ni.
cr Da ina ti ife mimo.
Li ori pepe aya mi.

2. Je k’ o jo f’ ogo Re nibe
Pelu owo ina aiku;
mf K’o ba ebo ati iyin
Pada goke si odo Re.

3. cr Jesu, mu fe okan mi se
N’ise l’oro l’ero fun O.
Ki nma so ina mimo na.
Ji ebun Re dide n’nu mi.

4. Ki nmura lati se ‘fe Re


Ki ntun se ise ‘gbagbo mi,
di Tit’ iku y’o f’anu Re han
T’ebo na y’o si di Pipe.
Amin.
752
S.M
Busi igbagbo wa Lk.17:5

1. mf Jesu, emi fe ri.


Itara Re n’nu mi,
Ajoanu Re f’ araye,
Ife gbigbona Re..

2. cr K’Emi Re gbe nu mi;


K’inu Re yo si mi;
Beni gbona itara mi.
Y’o je ife mimo.
Amin.
753
C.M
temi yoo ya wa kuro n’nu ife kristi Rom.8:35

1. mf Jeki Eni ti o ni wa,


Joba li okan wa.
K’O si gba orin ope wa
Ati gbogbo’ fe wa

2. Awa je Tire nitoto


Eni ra wa pada;
cr Toku taye onigbagbo
Ti kristi nikan ni.

3. cr Jesu, jowo gb’awon Tire


Mu ‘fe okan wa se
Je ki a wa fun ogo Re.
K’a ku s’enu se Re.

4. Tokan-tara wa l’afun O;
Gbogb’ohun ti a ni
f L’a fi fun O –tayo ,
Titiayeraye .
Amin.
754
8.8.8.D
Ni igbona okan re. E ma sin Oluwa.Rom.12:11

1. mp Oluwa , wo iranse Re;


Mas’ aifi oju Re to mi.
cr Ki ngbo, ki npa oro Re mo,
Ki nwadi, ki nsi se fe Re.
Ki nma se gbekele se mi.
Dsugbon ki nmu ododo se.

2. mp B’ or –ofe Re ba je lo mi;
Emi eni ninilari,
cr Yan se on akoko fun mi.
Je ki nso ninu Re;
Jekins’ise mi pelu Re.
Si ba mi se li asepe

3. p Ailera ni gbogb’ ero mi,


Se b’o ti to loju Re;
cr Jesu , kise mi je Tire;
Oluwa, pipe n ise Re.
Rere ni gbogbo ise Re.
Amin.

4. cr Mo f’ ara mi le O lowo ;
Se mi b’o ti loju Re
Fi ami Re si ara Mi ,
Si jeki nmu ore Re se.
mf Ki nsin O pelu Okan kan,
Ki nwa , ki nku fun ogo Re.
Amin.
755
11.11.11.11&Ref.
Emi wa ki won le ni iye, ani ki won le ni lopolop Jn.10.10.

1. cr O ha gbekele Jesu n’gbogb’ ona re


O ha nd’otun lokan re lojojumo
O ha j’om eyin Re; ye oro Re wo
Y’o fun O l’Emi mimo loplopo
mf Lopolopo si , lopolopo, si
Ki won le ni iye si lopolopo
Lopolopo si, lopolopo si,
Ki won le ni iye si lopolopo,

2. mf Fun oju rere Re,gbe oko Re ga,


Olugbala wa tot’orun sokale,
K’awon ayanfe Re juba oro Re.
Eni ra wa pada nipa eje Re.,

3. cr Wa pelu igbagbo , wa je ipe Re.


Eyin t’a mbukun, jowo ara yin fun;
Jesu , y’ogb eni t’o sa wa sodo Re
Y’o da ‘bukun Re lu o lopolopo.
Amin.
756
8.7.8.7&Ref.
Awon eni irapada Olua yio wa si Sioni ti awon ti orin , ikanu ati ofo yio fo lo.

1. f Korin t’ife ‘ yanu Jesu,


Anu at’or-ofe Re.
Yio pese ayo fun wa
N’ile Baba Re loke
Gba ta ba d’orun rere,
Bawo li ayo wa yo ti po to.
Gba ta ba ri Jesu.
Ao yo . ao korin Isegun.

2. mp B’a ti nrin lo l’on ajo wa,


Okun yo su l’ona wa,
f Laie oru ekun yo di
Oeuro orin ayo.

3. cr E je ka ma foriti lo.
Ka ma sin tokantokan;
f Ta ba ri ninu ogo Re,
Ao gbagbe iponju wa

4. f Tesiwaju, ese daju;


Laipe ao ri ewa Re;
Ao silekun ita wura
N’biti ao ma gbe titi
Amin.
757
11.11.11.11..
Eniti eyin fe lairi.I PET.1:8

1. cr Jesu, mo fe O, mo p’O je temi,


Mo f’aye ese sile nitori Re;
mf Iwo l’Olugbala, Olurapada;
Bi nko fe O tele n’siyi mo fe O,

2. cr Mo fe O n’tori’ Wo lo koko fe mi,


O ra dariji fun mi ni kalafri
Mp Mo fe O, Wo lo ade egun fun mi;
Bi nko fe O tele, n’siyi mo fe O,

3. mf Ni yiye tabi ni kiku un o fe O,


Un o fi gbogbo ojo aye mi yin O;
cr Nigba iku un o si ko orin yi pe;
Bi nko fe O tele , n’ siyi mo fe O;

4. mf Ninu ogo didan ti ainipekun ,


Iwo lemi o ma fiyin fun titi;
f Un okorin pel’’ ade ogo lori mi,
Bi nko f’ O tele ,n’siyi mo fe O,
Amin.
758
14.9.14.9.&.Ref.
A fi ipile re l’ori apta. Mat 7:25

1. mf A nkole l’apata t’ jijikiji ko le mi,


Pile wa daju o lagbara;
Ise wa nihin ni lati segun gbogbo ibi,
K’a si gbekel’ orisun ‘ranwo.
cr Apata
(A nkole l’or’Apata),
Apata,
(L’or’Apata to daju)
Apata ayeraye to duro lae (duro lae)
Apata
(Ankole l’or’Apata,)
Apata
(Apata to ni’bukun)
f A nkole l’or’Apata, kristi Jesu.

2. cr Ko si ‘pile ta fi sole lon’ aimokan wa


To le duro b’igbi’ ponju de;
f Sugbon lori krist’ Apata l’abo to daraju,
Nitori ike Re l’o daju.

3. mf Jeka sise, ka ko rin ninu temil’ mimo yi,


Ninu sin Re ao ri ‘bukun gba;
Ta ba f’ayo ati sowopo sise f’Oluwa
Wre wa ni ayo ailopin.
Amin.
759
7.7.7.D
Omo, lo sise loni ninu ogba ajara mi. Mat.21:28

1. mf Gbo b’ Olugbala ti wi
Pe ise po n’nu ogba;
Alagbase ko si to
cr O mura fun ‘se na bi
Afunrugbin funrugbin,
Oko pon, ikore de
Olukore mu doje
Lati ko’ rugbin wale.

2. f Olugbala nkew tantan


P’eyin onise dide,
Gbe ihamora mi wo
Mura fun ‘se lat’ oni
Akoko nsure tete,
Ojo ikore de tan
Olukore ti se tan,
Lati ko iti wole,

3. mf Wundia mewa la yan,


di Marun ko mura sile;
Marun to ti mura tan
Ba Oba Ogo wole.
cr Lo talent ta fi fun O,
Sise ‘ranse re loni
Foriti, itesiwaju,
Wo o gbade Isegun.

4. f Gbo ipe Olugbala,


Wa je ‘pe na nisiyi,
Mase f’akoko dola,
Ojo igbala de tan,
cr zOhun to npe nisiyi
Le dekun ipe lola,
Se’ pinnu rere loni
Ko le gba ade ogo.

5. mf Oluwa ,Olorun mi,


Un o fi ayo jise Re;
cr Fun mi ebun ahon,
Ki njise na laiberu;
Nigbayi li okan mi
Y’o ma korin iyin pe;
f Ti Oluwa Olorun
Ni iyin ati ogo.
Amin.
760
8.7.8.7.D.&.Ref.
Enu boe mejejila je pearli mejila Ifi.21:21

1. Mo fi won sile fun Jesu


Aye asan ko je nkan;
cr Gbogbo adun re bi egbin,
Gba mba ranti kalfari;
B’ore tile ko mi sile,
Ti o ku emi nikan;
mf Mo l’ore kan to wa n’tosi
Nigba ‘lekun pearl ba si.
mp Aye yi yo rekoja,
Orun re yoo si wo;
f Nko ni mo’banuje mo
Nigba ‘lekun pearl ba si.

2. mf Gba mo gbohun Jesu to npe,


At’ipe jeje angel,
Un oro mo Olugbala mi.
La afonifoji ja;
Un o d’ileri Re owon mu.
f ‘Ma beru , un o wa pelu re
Nigba ‘lekun pearl ba si’

3. mf Ni ikoja odo Jordan,


At’ afefe tutu Re;
N’igi iye, aiku ngbile
N’isura ainiye wa
Awon angeli si nduro
Nibi’lekun pearl si le.
Amin.
761
L.M
O siwaju won , awon agutan si nto lehin.Jb.10:4

1. mp O na t’o yan l’emi o to,


Tori mo gbeke mi le E.
cr Mo ranti pe nitori mi
Ni op se ku ni kalfari.
mf Jesu nto mil’osan l’oru
Jesu nto mi l’ona gbogbo
O je ore toto fun mi,
Tori mo ranti kalfari ,

2. Mo ti fean ase Re to;


Mo fek’owo Re ma to mi,
cr Ife rere Re ti dun to
T’o fihan l’oke kalfari.

3. f Mo nlo pel’okan diduro


Ninu kristi Olugbala;
Ni igbekele pe laipe
Un o ri Jesu ti kalfari.
Amin.
762
8.8.8.6.&. Ref.
E lakaka lati wo oju –ona koto Lk.13:24

1. mf Mo nla lati t’ona iye,


Lati tubo sunmo Jesu;
L’akoko danwo un oun obebe
Fun ore-ofe Re.
f A ore –ofe yi
To kun iyanu;
Ore-ofe yi to fun
Ohun gbogbo fun mi.

2. Ohun Re tun npe mi pada


Gba mo si f’ara mi fun U.
Mo ri ogo Re lara mi,
Ogo or-ofe Re.

3. mp Mo nwa krist’ mi lor’ekun mi


Ore –ofe li ebe mi.
Gbana li omije mo ri
Ogo or-ofe Re.
Amin.
763
7.6.7.6.D.
We mi nu kuro ese mi.OD.51:2

1. mf Mo kese mi le Jesu,
Odagutan mimo,
Oru gbogbo eru mi
O si mi d’omnira
Mo ru ebi mi to wa
K’O we eri mi nu,
cr K’ eje Re Iyebiye
Le so mi di mimo.

2. mf Mo k’aini mi le Jesu,
Tire l’ohun gbogbo;
O w’ arun mi gbogbo san,
O r’emi mi pada,
Mo ko ibanuje mi,
Eru at’ aniyan
f Le Jesu , O si gba mi,
mf O gba irora mi.

3. mf Mo gbokan mi le Jesu,
Okan are mi yi;
cr Ow’ otun Re gba mi mu,
Mo simi l’aya Re,
Mo fe oruko Jesu
Immanueli krist’
Bi orun didun yika
Ni oruko Re je.

4. mf Mo fe ki nri bi Jesu
p Ni rere at’ife;
mf Mo fe ki nri bi Jesu,
p Omo mimo Baba;
mf Mo fe ki mba Jesu gbe,
Larin egbe mimo,
cr Ki nkorin Iyin titi,
Orin t’angeli nko.
Amin.
764
C.M.&.Ref.
Nitori Emi ni Olorun re; Emi yoo fun o ni okun Isa .41;10

1. mf E mi ko le sai l’agbara,
Lkati olododo;
Tori Olorun mbe fun mi.
Lati ran mi lowo.
cr A mba le gbeke mi le E
Bi on ti wa nitosi,
mf On ko ni sai ran mi lowo
Y’o si pese f’aini mi.

2. mf Nko le sai l’ore toto


Jesu ni ore mi.
cr B’ore miran ko tile si.
Jesu fe d’opin .

3. Nko le sai ma l’ayo giga,


Ayo Re wa n’nu ko tile si.
Kukuru ni ayo t’aye,
Tire wa titi lae.

4. mf Nko le sai ma l’ohun gbogbo,


Olorun je gbogbo;
Mo nkorin ‘yin Re lojojo,
Mo npe oruko Re.
Amin.
765
11.7.10.8.&.Ref.
Gbe agbelebu ki o si ma mi lehin Mk/10:21

1. mf On’ agbelebu ni mo ni ba lo ‘le


Ko tun ona mi mo;
Un o ba ni de enu ona ogo na
Bi mo ba ona yi nu.
cr Ona lo agbelebu yi.
L’o lo si ile ogo (tara)
O dun ki mno bi mo ti rin lo pe
On nikan l’ ona ile..

2. mf Mo ni lati rin l’ona ta eje won,


Ona t’Olugbala rin.
Bi mo ba fe g’oke lo si orun.
Nibiti okan gbe nsimi.

3. mp Gbana un o ki aye pe, O digbose’


Un ko tun rin l’ona re mo;
Tori kristi duro l’enu ona
O si npe mi pe , Wa ma bo ‘
Amin.
766
11.8.11.8.&.Ref.
Pelu ipinu okan , e fi ara mo Oluwa Ise. A. 11:23

1. mf Gbati o ba nlo s’ile ‘simi orun,


Sunmo Jesu titi ‘oipn;
Tori oun ni Oluto t’o ona ju.
f Fara mo Jesu, fara mo jesu
S unmo Jesu titiopin.
Gbe apata ri ojurere Re
Sunmo Jesu titi d’ opin.

2. cr Mase ronu wahala at’iponju,


Sunmo Jesu titi d’ opin,
O dara lati ri ojurere Re’
Sunmo Jesu titi d’ opin.

3. Ki o ba bo lowo ofa esu,


Sunmo Jesu titi d’ opin.
Gbe apata igbagbo fu Isegun,
Sunmo Jesu titi d’opin.

4. f Awa y’o dele wa nigbose,


Sunmo Jesu titi d’opin.
Nibiti a ki wipe’d’opin;
Sunmo Jesu titi d’opin.
Amin.
767
9.8.9.7.&.Ref.
Awon ogun ti mbe li orun si nto lehin Ifi.19:14

1. mf Gbo iro opopo aye


Bi ti igbi omi okun ,
Ti nfi agbara re ru s’oke
T’o nkolu ebute.
Gbo iro ese omo ogun
Bi won ese omo ogun
Are won fun se at’ irin ajo
Ati ija kikoro;
Sugbon won gbagbo, won tejumo
Ona na t’awon gbagbo , won tejum
Ona na t’awon mimo ti rin ,
Bi won ti nlo ni ‘gbagbo
Won ndagba n’nu Olorun Alaye

2. Won ntesiwaju pelu ‘gbagbo


Ti ekoko ko le Olorun
Le sise f’aini gbogbo.

5. cr Dapo mo won , aye wa sibe,


Duro de ‘bukun Olorun;
Oun ni reti gbogbo agbaye
Lati sise ododo.
Amin.
768
7.7.7.3
E ma sona , ki e si ma gbadura , ki eyin ki o ma bo sinu idewo. Mat.26:41

1. Kristian mase jafaral;


Gbo b’angeli ti nwi
Ni arin ota ti wa,

2. f Ogun orun apadi


Ta ko ri nko’ra won jo;
Won nso ijafara re,
P Ma sora.

3. mf Wo hamora orun saju,


Wo ba l’osan ati l’oru;
Wuu ba, o nd’ ode re;
Ma sora.

4. mf Awon to segun saju,


Won now wa b’awa ti nja;
cr Won nfoi ohun kan wipe;
Ma sora.

5. f Gbo b’ Oluwa re wi,


di Eni ti iwo feran
p F’oro Re si okan re.
Ma sora.

6. mf Ma sora bi enipe
Nibe ni’ segun re wa,
Gbadura fun’ranwolowo,
Ma sora.
Amin.
769
7.7.7.7
Je alagbara ipa ninu , ati ninu agbara ipa Re.Efe.6:10

1. mf L’arin ewu, at’ osi,


Kristian, ma tesiwaju;
f Roju duro, jijja na,
K’ounje ‘ye mu o lokun .

2. f Kristian, ma te siwaju,
cr Wa ka d’oju ko ota ;
E o ha beru ibi?
S’’e mo ‘yi Balogun yin?

3. f Je ki okan yin baje ,


Mu ‘hamora orun wo;
cr Ja, ma ro pe ogun npe
Isegun yin fran de.

4. mp Ma je k’inu yin baje,


Oun y’o n’omije yin nu,
Mase je k’eru yin,
B’aini yin lagbara yin.

5. mf Nje ma tesiwaju
crEo ju asegun lo;
B’opo ota doju ko yin,
Kristian, e tesiwaju.
Amin.
770
C.M
Jesu wipe; Emi lo ona ati otito ati iye Jn.14:6

1. mf Iwo l’ona odo Re ni


Awa o ma sa bo;
Awon t’onsaferi Baba
Yoo wa s’odo Re.

2. f Iwo n’l’oto, oro Tire


mf L’o le f’ogbon fun wa;
Iwo nikan l’o le ko wa;
T’o si le we okan.

3. f Iwo n’iye; boriji Re


Fi agba Re han;
Awon t’ogbeke won le O,
Won bo lowo iku.

4. f Iwo l’Ona, oto, Iye


mf Jek’a mo ona Re;
K’ a mo otioto at’ iy,e
T’’ayo re ko l’opin.
Amin.
771
8.7.8.7.
O si wi fun pe; E ma to mi lehin lojukanna nwon si nto O lehin. Mat.4:19&20

1. mf Jesu npe wal’osan l’oru


Larin irumi aye;
Cr Lojjojumo kanbg’ohun Re
p Wipe ,”kristian, teke mi”.

2 mf Awon Apostel igbani


Ni odoi Galili ni;
Won ko ile, sile,
Gbogbo won si nto leyin.

3 Jesu npe kuro ninu


Ohun asan aye yi;
Larin afe aye O nwi;
p Pe:”Kristian efean Mi”.

4 mf Lrin ay at’ekun wa,


Larin lalla on rorun:
Tantan l’Ohun rara
p Pe:”Kristian efean Mi”

5 mp Olugbala nip’anu Re
cr Je ki a gbo ipe Re:
F’eti gboran fun gbogbo wa,
K’a fe O ju aye lo.
Amin
772
S.M
Enikeni ti a ti pa Olorun bi ki I dese 1Jn.3:9

1. mf Ki nma ba tun d ese


Ti Olorun mi ko;
Olouwa , se atunda mi
Si s’okan mi d’otun.

2. Nigbana l’okan mi.


Y’o korira egbin;
B’ife Re ti ya si mimo
Ki o si d’ese mo.

3. Ofin Re mimo ni
Jesu jo fi ko mi;
cr Ofin Emi nipa iye
Jo ko si aye mi.

4. Gbin sinsin sinu mi,


Ko ma le sipo lae;
Ofin ‘dande kruro ‘n’n ese,
Ofin pipe t’ife.

5. mf K’iwa Re je temi,
Iwa ailabawon;
Mo fa okan mi s’odo Re,
Ni wakati gbogbo.

6. f Wo ni ‘ye emi mi.


Oludande aye ;
Mu igfe Baba Re orun.
Se ninu aye mi.
Amin.
773
C.M
Da aya titun sinu mi, Olorun ;Ki o si tun okan diduro sinsin se sinu mi.

1. mf Olorun mo mo O n’temi,
Nki o fi O sile
’ Tit’ini mi yo di Tire
T’ao si so mi d’oun

2. mp Mo f’iwariri di O mu.
Nki o fi O sile;
Tit un o duro ore Re.

3. Gbawo l’akoko na yo de
Ti Wo yo gbe n’nu mi;
Emi iye at’ agbara,
At’ omnira pipe?

4. mf Jesu , tan ife asegun


Si inu okan mi.
K’ese mi mase yapa mo,,
K’o o mule ninu Re.

5. f Ina mimo iba je le


Gberan ni inu mi;
K’o jo idaro ‘fekufe ,
K’o si yo apata.

6. mp Ina iba je sokale,


K’o run gbogb’ese mi.
Wa Emi mimo je ‘pe mi.
Emi bi ina , wa

7. mp Ina atunse, wonu mi,


Tan , mole s’ okan mi ,
cr Fi emi Re kun gbogbo re,
mp K’o si ya si mimo.
Amin.
774
C.M
Emi o fi okan titun fun yin pelu Esek. 36:26

1. Mo fe okan laini ese,


Lati yin Oluwa;
di okan ti o mo eje Re.
T’a ta sile lo fe,

2. mf Okan suru to si tutu,


Ite Oludande,
Nibi kristi nikan nsoro,
Ti o nikan njoba.

3. mp Okan ‘rele ti nsa f’ese


To gbogbo to si mo;
T;iku tab’ iye ko ya
Ti O krist’ ti ngbe be.

4. mp Okan titun patapata,


To kun ‘fe orun ;
Pipe, tito ,mimo rere
Aworan Re , Jesu.

5. mf Oluwa f’iwa Re fun mi,


Jo sokale kankan;
Ko oko titun s’aya mi.
P Oruko Re t’ife .
Amin.
775
L.M.& Ref.
Sugbon eniti o ba fortiti titi de opin oun na li ao gbala Mat.24:13

1. mp Okan aare ile kan mbe


L’ona jinjin s’aye ese;
Ile t’ayida ko le de;
Tani ko fe simi nibe.
mf Duro, roju , mase kun (2)
Duro, duro, sa roju mase kun.

2. mp Bi wahala bo o mole,
B’ipin re l’aye ba buru,
W’oke s’ile ibukun na;
Sa roju duro mase kun.

3. cr Bi egun ba wa l’ona re,


Ranti ori t’a f’egun de;
B’ibanuje bo okan re,
O ti ri be f’ Olugbala .

4. cr Ma sise lo, mase ro pe


A ko gb’adura edun re;
mf Ojo isimi mbo kankan;
Sa roju duro , mase kun.
Amin.
776
L.M
Bi enikan ba nfe lati to mi lehin ki o se ara re ki o si gbe agbelebu re. Mat.16:24

1. f Gb’agbelebu re ni krist’ wi
B’o ba fe s’omo eyin Mi.;
Se ra re ko aye sile,
Si ma fi rele tele Mi.

2. mf Gb’agbelebu re, ma je ki
Iwuwo re fo o Laysa,
cr Ipa Re y’o gb’emi re ro,
Y’o m’okan at’ apa re le.

3. mf Gb’ agbelebu re ma tiju,


Ma je k’ okan were re ko.
P Oluwa ru agbelebu
Lai gba o lowo iku.

4. mf Gb’ agbelebu re n’ipa Re.


Rora ma la ewu ja lo;
cr Y’o mu o de ile ayo;
Y’o mu o segun iboji.

5. mf Gb’agbelebu re, ma tele,


Mase gbe sile ti’iku
Eni t’o ru agbelebu
cr L’o le reti lati d’ ade.

6. mf Wo Olorun Metalokan,
L’a o ma yin titi aye;
Fun wa, K’awa le ri n’ile
Ayo orun ti ko lopin .
Amin.
777
D.S.M
Sugbon e bowo fun kristi bi Oluwa li okan yin. pet.3:15

1. mf Jesu, agbara mi,


Iwo l’aniyan mi.
Emi fi igbagbo woke,
Iwo l’Ongbadura;
Jeki duro de O
Ki nle ife Re;
Ki Iwo Olodunmare
Ko so mi di otun.

2. mf Fun mi l’eru orun,


Oju to mu hanhan;
T’yo wo O n’gb’ese sunmole,
Ko ri b’esu ti nsa;
T’o ti pese tele;
f Emi to nduro gangan lae,
T’o nf’ adura sona.

3. Mo nfe f’owo to to
Fun oruko nla Re,
Ki nma ka ohun miran si
Lehin eyi nikan ;
Ki iyin Re aiku
Je oran edun mi;
Ki nma dupe ki gbogb’ aye
Ma yin or-ofe Re.

4. mf Mo gbekel’ oro Re
Wo l’o leri fun mi;
Iranwo at’ igbala mi.
Y;o t;odo Re wa se;
Sa je ki le mi ma ye;
Tit Iwo o fi m’okan mi
Wo nu isimi Re.
Amin.
778
7.6.7.6.D
Bi enikani nsin mi ki o ma tomi lehin.Jn.12:26

1. mp Jesu , mo ti se ‘leri
Lati sin O d’opin;
Ma wa l’odo mi titi,
Baba mi, Ore mi.
Emi k’y’o beru ogun
B’Iwo ba sunmo mi,
Emi ki yo si ona
B’o ba f’ona han mi

2. Je ki nmop’o sunmo mi
Tori baje aye;
Aye fe gba okan mi.
di Ota yi mi kalfari.
L’’ode ati ninu;
cr Sugbon Jesu sunmo mi.
Dabobo okan mi.

3. p Jeki nma Jesu gbo ohun Re,


B’ O ti mba mi soro ,
Larin iji idanwo ,
Aso at’agidi
cr So okan mi ni gbo Tire,
Wo Olutoju mi.

4. mf Jesu , Wo ti se ‘leri
F’ awon t’o tele O;
Pe ibibi t’o wa
N’iranse Re yo wa;
Jesu , mo ti se leri
Lati sin O dopin ,
Je ki nle to O leyin ,
Baba mi, Ore mi.

4. p Jeki nma ri, pase Re.


Ninle ma tele O;
Nipa ‘agbara Re nikan ,
Ni mo le tele O;
To mi pe mi, si fa mi,
Di mi mu de opin.
Si gba mi si odo Re.
Baba mi, Ore mi.
Amin
779
8.7.8.7.8.8.7.8.
Iwo ba kalo , awa o si se o ni ire.Num.10:29

1. ‘Eyin ero , nibo l’enlo,


T’eyin t’opa l’owo yin.
A rin ajo mimo kan lo,
Nipa ase Oba wa,
Lori oke on petele,
A nlo s’afin Oba rere
A nlo s’afin Oba rere
A nlo s’ ile to dara,
A nlo s’afinOba rere,
A nlo s’ile to dara.

2. Eyin ero, e so fun mi,


Ti reti ti eyin ni.
Aso mimo ,ade ogo,
Ni Jesu y’o fi fun wa;
Omi iye la o ma mu;
A oba Olorun wa gbe,
Ao ba Olorun wa gbe,
N’ile mimo didara;
Ao ba Olorun wa gbe
N’ile mimo didara

3. Ero , a le ba yin kegbe


L’ona ajo s’ile na
Wa, ma kalo , wa ma kalo,
Wa , si egbe ero wa,
Wa, emase fi wa sile,
Jesu nduro, O nreti wa,
Jesu nduro, O nreti wa,
N’ile mimo to dara;
Jesu nduro, O nreti wa.
N;ile mimo to dara.
Amin.
780
C.M
Enoku si ba Olorun rin.Gen.5:24

1. mp E mi ‘ba le f’ iwa pele


Ba Olorun mi rin;
Ki nni imole ti nto mi
S’ odo Od’agutan;

2. Ibukun ti mo ni ha da
Gba mo ko mo Jesu.
Itura okan na ha da
T’oro kristi fun mi

3. Alafia mi nigbana ,
Ranti re ti dun to
Sugbon won ti f’ato sile
Ti aye ko le di.

4. f Pada, Emi mimo,pada


Ojise itunu;
Mo ko ese t’o bi O n’nu,
T’o le O l’okan mi.

5. Osa ti mo fe rekoja ,
Ohun to wu ko je.
Ba mi yo kuro l’okan mi.
Ki nle sin ‘Wo nikan .

6. Beni un o f’ ifara bale


p Ba Olorun mi rin;
Mole orun yo ma to mi
S’odo Od’agutan .
Amin.
781
L.M
Enikeni ti o ba tiju mi , Omo eniyan yio tiju re pelu Mk .8:38

1. mf Jesu O ha le je be pe
p Ki eni kiku tiju Re
Tiju Re wo t’angeli nyin,
Ogo Eni nran titi lae.

2. Ki ntiju Jesu O san pe


Ki ale tiju irawo;
Oun ni ntan imole orun
Sinu okan okunkun mi.

3. Ki niju Jesu bakanna


Je ki oru tiju osan;
Okun oru bo okan mi.
K’irawo oru oro to tuka

4. Ki ntiju Jesu Ore ni.


Eni mo now lati d’orun
B’o ba ri be , k’oju ti mi,
Pe nko b’owo f’oko Re mo.

6. Un o ha hale lasan n’gbana


Pe mo l’Olugbala t’apa
f A k’eyi je isogo mi
Pe kristi ko si tiju mi.
Amin
782
15.9.15.9.&.Ref
Awon eni irapada Oluwayio pada , nwon o wa si Sioni ti awon ti orin .Isa 35:10.

1. mf O ti dun to lati mo Jesu Eni t’o gba mi la


Jojumo okan mi kun f’ayo,
Ayo ni lati ri pe O mba mi lo sibikibi ,
Jojumo ogo ni f’Oluwa,
f O ti dun to lati ma ba rin,
O ti dun ti lati ma ba rin,
Y’o ma se amona mi
N’nu mole at’ okunkun’
O ti dun to lati ma ba rin,

2. mf O ti dun to ki O wa nitosi nigba idanwo,


Ka sa gbagbo ka si gbadura;
O ti dun to kia ma gbe n’nu kristi nigbakugba
Y’o ma fi ogo orun kun wa.

3. mf Y’o dun to lati pade Re l’e ebute ogo na


Awa yo pade l’ainpinya mo.
Orin ogo, ogo , ogo la o ma ko titi lae
Ni ilu ologo ti Baba
Amin
783
L.M
Iyin Oluwa yio ma wa li enu mi titi lae. OD.34:1

1. mf O lorun , gbogbo ojo mi


L’emi o fi ope yin O,
Orin mi yo ba mole ji,
Y’o mu okan oru tuka,

2. mp B’aniyan fe ba simi je
T’edun fe ba mi n’inu je,
mf Orin iyin Re t’emi nko
Y’o ko ‘kedun na n’ijanu.

3. mp Gba ku ba bori ara mi,


Ti gbogbo ipa ede pin;
f Oju mi yo kun fun ayo.
At’ope temiko le so.

4. Sugbon gbat’ ija ‘keyin tan


T’ago ara ba bo sile;
Tayotayo ni un o goke
Lati gbe orin ti orun.

5. f Emi o ko orin giga


Ti ndun larin ode orun;
Em o f’ayo to apere
Awon angeli to y’ite ka

6. f Un oma sin O tayotayo


Bi emi mi yo ti wa lae;
Ise didun , orin giga,
Y’o je ipin ayeraye.
Amin
784
L.M
Sugbon awon ti o ba duro de Oluwa yio fun agbara won se. Isa 40:31

1. mf Ji, okan wa , k’eru wa lo


Ki ero ijaya wa lo;
Ji ko sare, ije t’orun
Ko si gbe’ gboya ayo wo.

2. di Loto, ona na kun f’egun


Are si mu emi eniyan;
mf Sugbon won gbagbe Olorun
Ti nf’agbara bo eniyan Re.

3. mf Olodunmare, ipa Re
Leke, o mbe l’otun titi,
Sinsin loduro , bi odun
Ti nyipo li ainipekun.

4. Lodo Re n’isun na ti nsan


T’okan wa yo ma mu , titi
Gba won to gbekele pa won
Yo yo danu , yo re, yo ku.

5. f B’idi nyara fo l’orun


Lao goke lo s’ibugbe Re;
Okan wa yo f’iye fe fo
Laise are lona orun.
Amin
785
C.M
Ki emi ki ole ma wo ewa Oluwa ki emi ki o si inu didun wo tempili re.OD.27:4

1. Ohun kan ni un o ma lepa


Pelu gbogb’ emi mi;
Oluwa se fun ranse Re
Ohun t’Emi Re fe.

2. di Fun n’ipo ni ile Re


Larin awon mimo;
Ki nle ma wo oju Re lae,
Ki nwole lese Re.

3. mp E wa oju mi B’o ti wi,


L’aise ijafara
L’okan mi f’ayo dahun pe;
cr Un o ma wa oju Re;

4. di Ma ko mi b’ ibanuje de,
T’adun aye fo lo’
Gbe t’obi on ara ko mi,
Olorun , ranti mi.

5. mp Nigbakuba ni mo ndaku,
Ti nko o si ni reti;
Sugbon ponju mu mi ranti
Ore Re atijo,

6. mf F’igboya duro d’Oluwa


Emi mi ye beru;
Onidajo ododo mbo
Irapada re de.
Amin
786
6.6.6.6
Ko mi li ona Re, Oluwa,
OD.27:11

1. cr O na Re , Oluwa,
B’o ti wu ko ha to
Fi owo Re to mi;
Yan ipa mi fun mi.

2. B’o rorun b’osoro,


Daradara lo je;
B’o wo ,bo to tara,
Lodo Re l’opin si.

3. cr Nko gbodo yan pin mi;


Nko tile je yan an;
Yan fun mi Olorun;
Ki mba le rin dede;

4. Ijoba ti mo nwa,
Tire ni; jek’ ona
T’o re be je Tire,
Bi beko un o sina.

5. mp Gba ago mi f’ayo


Tab’ibanuje kun
B’o ti l’oju Re;
P Yara retab’ ibi mi.

6. di Yiyan ti se temi
Ni nu ohunkohun ;
mf Iwo s’ Oluto mi,
Ogbon, ohun gbgogbo.
Amin
787
L.M
sa wo awa to O wa, nitori Iwo li Oluwa Olorun wa.Jer.3:22

1. cr O baniji, gbo ebe mi;


Je reti, ayo simi mi
Nipa ogo oruko Re
L’ao fi so mi d’alabukun .

2. di Rere ni O, at Ologbon,
Wo Baba at’ Olorun mi;
Tire l’emi, n’ife mimo,
Iranse Re f’eje ra.

3. di L’are okan , mo tewo mi,


Wo ni mo nwa, Wo ni mo now
Bi ero n’iyangbe ile
Ti nwa odo omi tutu.

4. mp Bi mba fi O ile Baba,


Ko le sanfani f’ okan mi,
Ife dariji l’ayo mi,
Oju Oluwa n’iso mi,

5. Un o gb’owo at’ ohun soke,


Niwon ti mo ba wa l’aye;
mf Ise yi yo fun mi l’ayo;
Y’o gba gbogb’ ojo aye mi.
Amin
788
C.M
Won si joko oro re. Deut yio gba ninu ore re.

1. mf Eni t;eje Jesu se;


Apa wa mo lowoJesu
A si nrerin ewu,

2. mf L’oniruru ona yanu


L’owo Re ndabobo
Awon mimo t’o agbekele
Ibala Re nikan .

3 cr Wli, Alufa , Oba wa.


Af’ayo juba Re.
A si ibukun gba eko
Li abe ese Re

4. mf Oro Re nfi iye fun mi,


At’ibukun orun,
cr Jeki mana ife bo ,
Amin.
789
7.6.7.6.6.6.6.5.&Ref
Emi ko je fi o sile ,beni Emi ko je ko sile Herb.13:5

1. I ba jafonfoji
B’I t;opo ewu wa;
Iba je ninu mole
Ti mo wa l’alafia;
Ohun kan yi daju;
Mp B’okunkun tile su,
mf Bi Jesu pelu mi
Ko s’ewu nibe.
mf Bi Jesu pelu mi,
Un o lo bikibi;
Ibiti mo ba wa orun lo je
B’O wa nibe;
Anfani ni lati ru agbelebu Re
Bi Jesu pelu mi
Ko s’ ewu nibe.

2. A le ran mimo lati


Kede oro iye
Fun awon ti o sonu,
Ti npafo n’nu ese.
Ohunkohun to de,
Nipa Igbaoran yi
Bi Jesu ba mi lo
Ko s’ewu nibe.

3. mf B’o Oluwa pe mi lati


Se ise nitosi
Nigbati opo nsise
Fun Un l’ona jinjin;
Un o fi gbagbo mi han
N’nu dajop Re gbogbo
Bi On duro timi
Ko s’ ewu nibe.

4. mf Ki ise fun mi lati


Yan l’Oluwa lowo;
Temi mi lati lo si
Ibiti O ndari mi;
Ibiti O wu ko je,
Nihin tabi Lorun ,
Un o wa pelu Jesu
Ni itelorun
Amin
790
11.10.11.10.
Oluwa yio fi alafia busi awon eniyan ati Re.OD.29:11

1. mp Nigbati ijiji nla nfe lori okun,


T’ibu yehannna alariwo nla,
Ni isale okun alariwo yi
P Idakeroro, alafia njoba.

2. mp N’isale lohun ariwo igbi ku,


Nibe nkorin titi aye
Bo ti wu kiji oke ti le po to,
K’o le ba simi sale okun je.

3. mf Be lokan to mo ife Kristi Jesu ,


Tempili mimo kan wa ta soto;
Gbogbo’ ariwo ohun ibinu aye
P Dake jel’ona alafia re.

4. mp Lona ijinjin, ariwo ibinu ku,


Ero ife sun l’alafia,
mf Bo ti wu k’iji ti lefo sokale to,
f Ko le damu okan to ngbe n’nu krist’
Amin
791
7.6.7.6 &.Ref.
E fi ayo sin Oluwa. OD.100:2

1. f Je oloto s’ Oluwa
T’o f’emi Re fun O;
Ninu ewu at’ ibi,
Je akoni toto,
mf J’oloto si Jesu,
Gbo asia Re soke n’bi gbogbo
J’oloto si Jesu,
Je akoni lati sise;
cr Nigbati ija ba si le
Gbekele Olorun Re;
Sise rere;
mf Korin ‘yin Re;
J oloto s’ Oba re

2. J’oloto nibikibi,
L’ojo tabi l’erun,
N’igbadun n.irora,

3. mp Msae sise imele,


mf Duro gbonin, n;ipa Re
Mu orona yara de
Tao ni segun pipe

4. f J’oloto bi agbara
Okunkun yi o ka;
Angel Re y’o ma so O.,
Ipa Re l’orin re.
Amin
792
C.M.&.Ref.
Nigbana niba won wa si ibi kan ti a npe ni Genestemane. Mat.26:36

1. mf Oba aye mi, mo yin O,


Iwo l’ogo ye fun;
Ki nma bna gbogb’ ade egun,
cr To mi si kalafi,
mf Ki nma gbagbe Getsemane,
Ki nma gbagbe iya t’o je;
Ki nma gbagbe ife nla Re
cr To mi si kalafri .

2. cr Mu mi ranti ranti iboji Re


Nibiti Iwo sun ;
Nibe angeli yi O ka,
Won si nso Oba won.

3. crJekinmu ebun wa fun O


Bvi Maria ti se;
Ki nje awoko ife Re,
To mi si Kalafri.

4. cr Fun mi n’ife ki nle ma wa


Awon ti ko mo O;
Fi Emi Mimo kun ‘nu mi
Ki nso ti Kalafri.
Amin
793
10.10.10..8 D
Eyin ni imole aye. Mat 5:14

1. mf Mo fe ki nje imole fun Jesu


Nibikibi, ki nfi ewa Re han,
Ki nma dagba n’nu or-ofe Re,
Ki ntan imole,Re l’aye
f Ki ntan imole, ki ntan imole,
Ki ntan mole ife atorunwa;
Ki nmaf’ogo fun l’osan at’ eru,
Ki nma tan ‘mole fun Jesu.

2. cr Mo fe ki nje imole fun Jesu


Ninu ayuo tabi ibanuje;
Ki nje ranlowo f’awon t’eru npe,
Ki nje imole tan ‘mole fun Jesu.

3. Mo fe ki nje fun Jesu,


Imoile ninu aye ese yi;
Ki nmu awon ti nsako pada bo,
Ki nma gbe oruko Re ga.

4. mf Mo fe ki nje imole fun Jesu,


Ki nfi tayotayo sure ‘je mi;
Ki ngbekele or-ofe Re nikan
Titi un ofi ri oju Re.
Amin
794
1.11.11.11.&.Ref
Emi o ma too lehin nibikibi ti iwo nlo,
Mat.3:19

1. mf ‘Bikibi ti Jesu wa , ewu ko si,


Bikibi t’O to mi n’nu aye yi;
cr Laisi Re ayo kan wa, eru ko si,
f Bi kibi ----- pelu Re kili ao beru
Bikibi ti Jesu wa, ewu ko si.

2. mf Bikibi pelu Jesu ayo lo je,


B’ore miran ko mi, On ko je ko mi,
cr Bo tile mu koja isan danwo,
Bikibi pelu Jesu ayo lo je.

3. mf Bikibi pelu Jesu ni mo le sun,


B’o tile okunkun yi mi ka;
f Mo mo pelu pe un o ji si iye pelu Re;
Bikibi ti Jesu wa, ile je.
Amin
795
C.M
Sugbon emi nlepa nso Fill3:12

1. mf T’ Olorun mi emi yo se
B’gbogbo ona mi,
B’aye tile dide si mi,
Krist’ yo j’aworan mi.

2. T’Olorun mi emi yo se’


mp Bi ogun tile nja;
Gbat’ara ore ba ko mi,
mf Baba yo di mi mu

3. T’Olorun ni emi yo se
L’ ero at’ iwa mi;
Ninu oro tabi ponju ,
Jesu yo s’ ara mi.

4. Ninu idamu aye yi,


L’emi yo ro mo O,
mf F’owo otun ododo Re
Gb’emi omo Re ro.
Amin
796
L.M
E lakako lati wo oju kot Lk.13:24

1. mf Emi nlepa l’ojjojumo,


Mo si tun nlakala pelu;
Ki nle jogun ibugbe na
Ti Jesu ti pese fun mi

2. mf Emi nnoga l’ojojumo.


Lati ri pe owo mi re
Ade ologo ti ndun ni.
T’a se l’oso fun ayanfe

3. mf Emi nreti l’ojojumo


Lati gbo ohun ayo ni.
Gbati mba siwo ise pe;
Bo sinu ayo Baba re.

4. cr B’aye tabi awon ore


Ba le fa mi s’ona egbe,
Jeki nle f’igboya so pe;
f T’emi ni Jesu, un o ba rele.

5. cr Wo oluwa Olorun mi.


Mu mi segun eran ara’
K’emi ma kose, subu
Kuro lona ile ogo.
Amin
797
C.M
Gbo adura mi, Oluwa OD 102:1

1. mp Baba alanu t’o fe wa,


Mo gb’okan mi si O;
mf Ipa Re t’o po l’o gba wa
Awa nkorin si O.

2. f Tire papa l’awa fe se


Gb’ okan wa fun ebo;
O da wa, osi tun wa bi,
A f’ara wa fun O.

3. Emi Mimo , wa sodo mi,


F’ ife Oluwa han;
Fun mi k’emi k’o le ma rin,
N’ife Oluwa mi.
Amin
798
L.M
Ma rin niwaju mi ki iwo ki o si pe, Gen.17:1

1. f Mo f’ igbagbo b’ Olorun rin


Orun ni opin ajo mi;
Op’at ogo Re u mi n’nu’
Ona didun l’ona l’o la.

2. f Mo nrin aginju nla,


p Nibi opolopo ti mu;
Sugbon on’ t’o samona wa
Ko je ki nsina, ti mba nu.

3. Mo nla kekun l’
Aye at’ Esu kolu mi;
Agbara Re ni mo fi la,
Igbagbo sini ‘segun mi;

4. p Mo nkanu awon ti nhale ,


F’aye ti nkoja yi;
f Oluwa je ki mba O rin,
Olugbala at’ ore mi.
Amin
799
8.7.8.7.&.Ref
Alabukun funnieyin ti nfonrugbin nina omi gbogbo.Isa 32:20

1. f Ara mi fun ‘rugbin rere,


Nigba ifurugbin wa,
Ma sise l’oruko Jesu
Tit’oun o tun pada wa,
ff Nigbana ni a o f’ayo ka a,
Olukore a ko won si aba,

2 f Olugbala pasewipe,
‘Sise nigbat’o j’osan
Oru mbowa ‘mura giri,
Oloko fere de na

3 T’agaba t’ewe jumo ke,pe,


‘Wo l’oluranlowo wa,
Mu ni funrugbin igbagbo,
K’a s’eso itewogba,

4 mf Lala ise fere d’opin,


Owo wa fe ba ere’
B’O de ninu olanla Re,
Y’o so fun wa pe, ‘Siwo’
Amin
800
12.12.13.11..&.Ref.
Awon ti nla , fonifoji omije lo, won so o di kanga, akoro, ojo si fi bukun bo o, OD 34:6

1. mf Un o ba Oluwa mi lo si eba odo


Nibiti omi tutu yoyo nsun jade;
Ibikibi ti o ba mi si un o lo
Un o ma tele ipase Re de opin .
f Tele, un o ma tele Jesu
Bikibi ti O nlo l’emi o tele
Tele, tele un o ma tele Jesu
Bit’ O ba to mi si l’emi o ba lo.

2. Un o ba Oluwa mi lo si eba odo


cr Nibiti iji nla, ti okunkun si su;
Gbati owo Re nto mi, eru kole ba mi,
mf Ko si ewu bi Jesu wa nitosi .

3. f Un o ba Oluwa mi lo si ibikibi ,
Leba Oluwa mi li okan mi nfe gbe
Y’o ma samona mi li ona ti on ti rin
Titi d’ oke giga, Ilu Olorun.
Amin.
801
C.M
To omode li ona ti at’ to Owe 22:6

1. mf Olorun ogbon at ore,


Tan mole oto Re,
Lati f’ ona toro han wa,
Lati to sise wa;
2. mf Lati to wa koja larin
Apata l’agbami;
K’oko wa le rin laisewu,
K’a gunle l’alafia

3. mf Ore-ofe Re l’oko wa
B’a ti ko elomi,
A fe to awon omo wa
Ni gbogbo ona Re

4. mp Ifekufe on gberaga,
K’a pa run ninu won;
K’a fi ona mimo han won
Si Olugbala won.

5. mf K’a ma wo O nigbakugba
Fun apere lati
Ko wonm n’iberu on reti;
Ko won l’ero pipe,

6. mf Kaf’ itara pele ko won


Lati ma se gboran;
K’a ma f’ikanra se ohun
Ti a ba f’ ife se

7. cr Eyi l’a f’igbagbo bere ,


Ogbon lat’ oke wa.
Ti y’o f’eru omo kun won,
Pelu ife mimo,

8. di K’a fa won kuro l’afe;


K’a ma f’ibi bo won ;
K’a jeki okan odo won
Te soso Olorun.
Amin
802
8.6s
Bi o se temi ati ile mi, Oluwa o sin. Jos24:15

1. mf Emi at’ ara ile mi,


Yoo ma sin Oluwa wa
cr Sugbon sin emi papa
Yoo f’ iwa at’ oro han,
Pe mo mo Oluwa t’orun,
Mo nf’ okan toto sin.

2. mf Em’ o f’ apere re le le
Un omu idena na kuro
Lodo om odo mi
cr Un o f’ ise won han ni iwa mi
Sibe n’nu se mi ki nsi ni
Ola na ti ife.

3. Emi ki y’o soro gb’ ipe


Emi y’o pe tu ninu
Om’ eyin Olorun
cr Mo si fe je eni Mimo
Ki nsi fa gbogbo ile mi
S’ oju ona orun.

4. cr Jesu , b’o ba da ‘na fe na


Ohun de t’ Iwo fe lo,
Gba s’ owo ara Re
Sise ife rere n’nu mi
Ki nfi b’onigbagbo toto
Ti ngbe l’aye han won,

5. cr Fun mi l’or’ ofe toto


Nje Emi de lati jeri
Yanu oruko Re
Ti o gba mi lowo egbe
Ire eyi t’amo l’okan
Ti gbogb’ahon le la

6. mf Emi t’o bo lowo ese,


Mo wa lati gba le mi la
Ki nwaju dariji;
F’omo f’aya f’omo ‘do mi,
Lati mu won to ma rere
Lo si orun mimo.
Amin
803
C.M
Oju Oluwa mbe nibi gbogbo, Owe 15:3

1. mf Ise gbogbo ti awa nse,


Ni Olorun ti ri;
Ero gbogbo t’o wa ninu,
Ni Olorun si mo.

2. mp A ko le f’ ese wa pamo.
Gbogbo won l’o ti mo;
A npruo, antan ‘ra wa je
B’ a ro pe ko mo wa won

3. Ohin gbogbo han ni gbangba,


Ni oju Olorun ;
Okunkun ati imole ,
Si ri bakanna fun.

4. f Olorun , je k’a ranti pe


Oju re si ri wa;
Si je ki awa k’o beru.
Lati ese si O,

Amin
804
10.4.10.4.10.4.
Sugbonife ti emi ko bikose Tire ni ki a se. Lk.22:42

1. mp Oluwa , Olorun mi . se fe Re
Nki o mi ra,
P Owo ni dide, ki nma ba sesi ta owo na nu,
Ti nmu mi ro mo aya Baba mi
Ni isimi.

2. mf Okan ti nj ijakadi ni kristi


Nfun l’agbara;
P Iwaya ija Re oru gbati
Ko s’ enikan ,
Ju Baba , at’ angeli rere kan
Ti nt’ U ninu

3. mp Baba fe mi ko , Tire ni k;ase


Be l’omo wi,
cr K’eyi j asiri wa larin gbogbo
Lala aye,
P K’a le ro mo aya Re titi lae
Ni isimi.
Amin
805
8.8.8.5.&Ref.
Emi ni Aifa ati omega li Oluwa wi.Ifi.1:8

1. mf Mo fi gbogbo okan mi tan


Eni t’o le gb’ emi mi lae
Abo nla , ti ye lae
f Oro Re daju
f Emi l’Alfa, at’ Omege
Ipilese ati opin,
Ti O wa , t’o wa
Ti o si mbo wa,
Emi l’Alfa at’ Omega
Ipiliese ati opin
Olodunmare, Olodunmare
L’Oluwa wi,

2. f Okan mi nso pelu ayo,


Ti Eni ti ngbe inu mi,
Ifeni ti nteloto Re,
Lati mu duro.

3. cr Jehofa Olorun , Egba mi


Lowo ‘yemeji at’ eru
Fi gbagbo gbigbona fun mi,
M’okan mi duro.
Amin
806
7.7.7.7.D.
Olorun mi , eniti emi gbekele OD.91:2

1. mf Sa gbekele l’ojojo,
Gbekele l’arin danwo,
Bi gbagbo tile kere
Gbekele Jesu nikan.
f Gbekele ni gbagbogbo
Gbekele lojojumo;
Gbekele lonakona,
Gbekele Jesu nikan.

2. mf Emi Re ntan imole


Si ona okunkun mi;
Lowo Re , nko le subu
Gbekele Jesu niukan

3. B’ona ba mo Un o korin
cr B’o ba di, un o gbadura;
Larin ewu, un o ke pe,
mf Gbekele Jesu nikan.

4. Gbekele titi d’opin.


Tit’ aye o fi koja;
Ti ao si de nu ogo.
Gbekele Jesu nikan
Amin
807
7.6.7.6.D
E gba ajala mi si orun nyin ; ki e si ma fun okan nyin Mat.11:29

1. cr Gbati danwo yi mi ka,


Odo krist’ ni mo nlo;
mf Ni okan mi paya fun,
Ibi isadi mi;
Mo s’ okan mi paya fun,
O mo ti nso nkan mi;
f Bi mo ti nso nkan wonyi,
O m’edun mi kuro.

2. mp Gbati mo kun un eru


Ti mo nsunkun pere,
Mf O tan ibanuje mi,
O le eru mi lo;
Orewu t’o I mi ka,
Ati ailera mi;
f O fun mi l’ohun ija
Lati segun ese.

3. f L’odo kristi ni un o lo
Nib t’o wu ko je;
Un o se ma wo oju banuje
Odaju pe tabi ‘ banuje
mp Gb’ ayo tabi banuje
mf Ohun to wu ko je;
Odo Re sa ni un o lo,
Oun y’o si to mi wa.
Amin
808
13.13.13.13..&.Ref.
Eyi ha ise nko akoko atigba fadaka ati lati gba aso.11A,Oba 5:26

1. mf Oluwa nko bere fun fadaka onwura


Un o jijija kadi f’orun un o si wo si wo nu agbo
So fun mi, Oluwa mi ooko mi ha wa nbe
cr Ooko mi ha wa mmbe
Ninu iwe nla ni
Iwe ti ijoba RE
O oko mi ga mbe,

2. mp Oluwa ese mi porin okun


Sugbon eje Re , Jesu tilo fun gbogbo re
Tori Wo ti se leri ninu oro Re pe,
B’ ese re pon ododo , un o fo won fun bi sno,

3. f Ni lu daradara ni, ibugbe imole,


Nibi t’awon mimo wa, ninu aso funfun won
T’ohn eri ko le de lati b’ewa re je
N’bi t’awon Anfeli nso , ooko mi ha wa mbe.
Amin
809
6.6.9.6.6.9.&.Ref.
Enoku si ba Olorun rin. Gen 5:24

1. mf Gbat’ a ba ‘Oluwa rin


N’nu mole oro Re;
Gbat’ a ba nse fe Re,
On y’o ma ba wa gbe,
Ati awon t’ ogbekele won le
f Sa gbekele,
Ona miran ko si
Lati l’ayo n’nu Jesu,
Ju pe, ka gbekele.

2. mf Ko s’ ohn to le de,
Loke tabi n’ile,
To le ko agbara Re l’oju;
cr Iyemeji , eru
Ibanuje, kun.
mf Ko le duro , bi a gbekele.

3. f Ko si wahala mo,
Tabi ibanuje,
O ti san gbogbo ‘gbese wonyi
Ko si iaro kan mo,
Tabi ifajuro
Sugbon bukun b’a ba gbekele.

4. A ko le f’enu so
Bi fe Re ti po to
Titi ao fi f’ ara wa rubo;
mf Anu ti O nfi han
At’ayot’o O nfun ni
Je ti awon ti o gbekele.

5. Ni dapo pelu Re.


Ao joko l’ese Re,
Tabi ki a ma rin pelu Re
Awa yo gbo Tire,
Ao jise t’o ran wa
f Ma beru , sa gbekele nikan.
Amin
810
9.9.7.7.9.&.Ref.
Ko si enikan ti o ni ife ti o tabi ju eyi lo pe enikan fi emi re lele nitori awon ore re.Jn15:13

1. cr Jesu l’ore to dara julo


Gbati gbi aye yi lu O;
Y’o wo okan to gbogbe,
Y’o swi fi agbara fun;
Jesu l’ore to dara julo,
mf Jesu l’ore to dara ju
Jesu l’ojojo
Jesu l’ore to dara ju
Jesun’bigbogbo
On ki yo ko subu
Y;o gbo gbati o ba pe;
Jesu l’ore dara ju lo.

2. mf Ore pataki ni Jesu je,


O f’ alafia kun okan mi,
Ni gbekele apa Re
Nko je beru ibikan;]
Jesu l’ore to dara julo

3. mp Bi banuje tile de ba mi
Ti igbi jordan si nyi lu mi,
mf Emi kogbodo beru,
Oluwa mbe nitosi ;
Jesu l’ore to dara julo.

4. f Gbati a ba dele wa orun


` Pelu awon to ti lo saju,
Ao korin l’ebute Re
Ao si ma yin l’titi;
Jesu l’ore to dara julo.
Amin
811
8.7.8.7.&.Ref.
E si kiyesiil Emi wa pelu nyin nigbagbogo Mat28:20

1. mf I bi kan wa, ti mo feran


Gba t’okan mi poruru;
Ki nwa pelu kristi nikan
Ti O wipe’ wa simi’
Ki nwa pelu Jesu nikan
Ki ngbohun jeje Re pe;
f Mase beru b’aye ko o;
Emi wa pelu re’

2. mp Gba t’eru aye ba wuwo,


Ti o si te ri mi ba
Un o lo sodo Jesu nkan
Tori ore mi ni oun.

3. cr Gbati esu nfe lepa mi,


mf Jesu wipe ki nsa wa
Oun ni abo at’ ore mi,
Oj’ohun gbogbo fun mi,
Amin
812
L.M
E tujuka ,mo ti segun aye. In 16:33

1. Isegun wa li okan mi,


Nitori Emi ngbe nu mi;
Je ki igbi idanwo de,
Jesu mura lati gba mi,
ff Isegun , segun l’okan mi,
Mo ni isegun nla tori Jesu gb;okan mi
Isegun . Isegun ni odo sisan,
Mo ni segun nla ninu eje Jesu.

2. cr Bi ja tile le to si pe
B’esu tile b’okan mi ja;
mf Sibe mo je alagbara ;
f L’agbara Jesu , ngo segun.

3. f Mo ni segun lori es;


Mo ni segun lori boji,
Ani iku ko ni pa mo,
ff Aleluya emi ti la.
Amin
813
8.8.10.7.&Ref
E tujuka e ma beru Mat 14:27

1. cr Iji lile le ja yika ,


Ki danwo kikan sunmo mi,
mf Nko je beru b’ Oluwa sunmo mi,
Ti mo ngb’ohun ife Re
f Ko si nkan to le fo mi laya,
Gba mo ba wa n’nu Re
Wa n’nu Re
Itnunu at’ iranwo mi,
Jesu ta kan mo gi,

2. mp Eniyan nle ba mi n’nu je,


K’aniyan aye damu mi;
mf Sibe un o gbekele Oba l’oke ,
Un o fi gbagbo n’nu Re han.

3. B’imo yi ko tile ye mi,


mf Sibe oro Re pa lase
Ki ngbekele nipa nikan,
On yo tun ona mi se.
Amin
814
11.12.11.10.&Ref.
Nitoto oun o gba o lowo ikekun awon peyepeye.OD.91:3

1. mf Eru ji o ba mi won yoo dekun ;


Danwo ko le pa mi, tori mo l’alafia;
Gbogb’ohun ti mo ko sile , nko fe mo,
Un o r’ohun to ju won lo ni kenana.
f Awon to fe le duro n’Egypt,
Emi nlo si kenan’
Bnibi wara at’ oyin at’ alafia je temi;
Lehin ajasegun , at, alafia je temi;
Okan mi yo simi l’ebute Re

2. mf Wahala ko ni pa , ko le duro pe;


Won le wa yi mi ka un o sa s’odo Jesu;
Ko si iji ni ebute kenan’

3. mf N;nu opo ojiji ore –ofe, emi fe wa


Liabe ojiji ti kenan’ ti o pe;
Gbogbo ‘ gbekele mi le ye ko je nkan;
Ko s’ohun to le se mi ni kenan’
Amin
815
11.11.11.11..&.Ref.
Awa ju eniti o segun lo, nipa eniti o fe wa.Rom.8:37

1. f A segun ati ajogun ni a je


Nipa eje kristi a ni isegun ;
B’ Oluwa je tiwa , a ki yo subu;
Ko s’ohun o le bori agbara Re.
f Asegun ni wa , nipa eje Jesu;
Baba fun wa ni segun , nipa eje Jesu;
Eni t’a pa f’ elese
Sibe , O wa Onjoba;
ff Awa ju asegun lo,
Awa ju asegun lo,

2. f A nlo l’oruko Olorun Israel


Lati isegun ese at’ aisododo;
Kise fun wa, sugbon Tire ni yin.
Fun ‘gbala at’ isegun ta f’eje ra.

3. f Eni t’O ba si segun li ao fi fun,


Lati je mamato t’orun wa nihin
L’orun je mama si gbe imo pe asegun ,
Yo wo so fun si ti gbe imo dara.
A min
816
10.10.7.10.7.& Ref.
Aye si nkoja lo yio duro ifekufe re.sugbon eniti o ba mse ife Olorun ni yio duro
laelae.Ijn.2:17

1. `mf B ‘aye ba nfa mi pelu ogo re,


ko s’ewu, omo Olorun ni mi,
f Owo agbara Re yo di mi mu,
L’ojo aye mi gbogbo .
Mo l’ore t’o npese f’alai gbogbo,
Mo n’ile kan loke orun giga,
Wo mitori idi eyi na ni,
f Emi se nko Aleluya.

2. cr Emi ko je gbagbe lor’igi,


Ni omo Olorun gbe ku fun mi;
Ko le saiku lati gb’okan mi la,
Ko tun si ona miran.

3. mf Un o joloto s’Olouwa Oba mi,


Un o ma korin yin si nigbagbgbo,
Mo mo pe mikaehin , on yo gba mi,
Lati ma ba titi
Amin
817
8.7.8.7.&.Ref
Oluwa ni mo .bere mi le.OD.11:1

1. mf Ki ngbekele Olugbala ,
cr Ki wahala to yi mi ka
Mu mi sunmo odo Re
f Gbekele ojiji RE,
gbekele to titi
Gbekele Jesu ttiti
Ohunkhun to de,
Gbekele Jesu nikan

2. mf Ni gbekele ojiji Re,


Nigbati won ko si.
Mp Ilo ti wu k’oju oru orun su
mf Ife Re yo tan mole.

3. mf Gbekele imole Re Lae


Ko yemeji at’ eu;
Lori oke pelu Jesu
Gbe okan oke re s’oke.
Amin
818
9.8.9.7.&.Ref
Sugbon emi ki yo pese ki yo gbabe re Isa 49:15

1. mf Nigbati ona dba sokun,


Ti ojo ibi ba si de
cr Emi nranti ileri Tire.
mf On ko je gbagbe Tire
On ore ko je gbagbe Tirer
cr Bi ore sa, on wa gbabe Tire.

2. mp Nigbati reti gbogbo ba Jesu ba pin,


T’iyemeji at’ eru de,
Un o wa .isimi l’aya Eni ti
Ko ko je gbagbe Tire

3. f On ko je gbagbe Tire laelae ;


O se owon fun mi pupo ,
Lati gbani o ti sokale ,
Ti o o ngbe nu okan mi.
Amin
819
10.10.11.11
Alabukun fun li awon ti ko ri mi won si gbagbo .Jn.20:29

1. f Aigbagbo bila Temi l’Oluwa ,


On O si dide fuin igbala mi;
Ki nsa ma agbadura , on O se ranwo ,
Gba krist wa lodo mi ifoya ko si

2 p B’ona mi ba su, On l’o sa ntoi mi,


Ki nsa gboramn sa, On o si pese;
Bi iranwolowo eda gbogbo saki,
Oro t’enu Re so , yoi bori dandan.

3. mf Ife t’O fi han ko je ki nro pe


Y’o fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si nri lojojumo,
O nki mi l’aya pe, emi o la ja.

4. p Emi o se kun tori iponju,


Tabi irora , O ti to rele
Mo ni oro Re o’awon ajogun gbala,
Won ko le sai le koja larin wahala,

5. p Eda ko le so kikoro ago


T’Olugbala mu k’ese le ye;
Aye Re tile buru ju temi lo;

Jesu ha le jiya , kemi si ma sa

6. mf Nje b’ohun gbogbo ti nsise ire ,


Fun awon to duro de Oluwa ,
B’oni tile koro sa ko ni pe mo.
ff Gba na orin segun yio ti dun to.
Amin
820
10.10
Iwo o pa mo alafia pipe. Isa 26:3

1. mp Alafia li aye ese yi


Eje Jesu nwipe , Alafia’

2. mf Alafia ninu opo lala;


Lati se ife Jesu ni simi .

3. Alafia n’nu igbi banuje?


L’aya Jesu ni dake roro wa.

4. mp Alafia , ba gb’ara wa wa l’ajo


Ni pamo Jesu iberu ko si.

5. f Alafia , ba ko tile m’ola


A mo pe Jesu joba titi lae.

6. mp Alafia nigb’ akoko iku;


Olugbala wa ti segun iku.

7. di O to jakadi aye fere pin ,


Jesu y’o pe wa s’orun alafia
Amin
821
6.64.6.6.6.4.
Oju wa now Oluwa Olorun wa.OD.123:2

1. f I gbagbo mi Wo O
Iwo Od’agutan
Olugbala ,
P Jo gbo adura mi ,
M’ese moi gbogbo lo;
cr K’emi lat’ oni lo
Si je Tire.

2. mf Ki ore-ofe Re
F’ilera f’okan mi;
Mu mi tara;
P B’iwo ti ku fun mi,
cr A k’ife mi si O,
K’o ma gbona titi
B’ina iye.

3. p Gba mo nrin l’okunkun


Ninu Ibanuje,
cr S’amona mi,
So ‘okun di ‘mole;
Pa ‘banuje mi re,
Ki nma sako kuro
Li odo Re.

4. p Gba ti aye ba pin,


T’odo tutu iku
Nsan lori mi,
Jesu , ninu ife,
Mu k’ifoya mi lo,
Gbe mi d’oke orun.
B’okan t’ara.
Amin.
822
6.6.8.8.8
Nitori Emi li Oluwa, Emi , ko yipada Mat3:6

1. mp Nihin l’ayida wa;


Ojo , erun , nkoja,
Di ile ni nyin ti o si nsa,
Tanna dada si nre;
f Sugbon oro pelu re kristi duro;
Un o wa pelu re ‘ ni on wi.

2. mp Nihin l’ayipada wa
L’ona ajo orun;
N’nu gbagbo reti at’ eru
N’nu fe Olorun wa;
Di A nsaika oro yi si po
Un o wa pelu re ni kristi wi

3 mp Nihin l’aiyda wa.


cr Sugbon l’arin eyi;
L’arinayidayid aye,
f Okan wa ti ki yi ;
ff Oro Jehofa ki pada
Un o wa pelu re ni on wi.

4. mp Ona alafia ;
Immnuwli wa
ff Majemu ti ore-ofe,
Lae , won ki pada
cr Nki yi pada ‘ l’oro Baba,
Mo wa pelu re ‘ ni on wi
Amin.
823
C.M
Ipae Re lia ko si mo OD.77:19

1. mp Oona ara l’Olorun wa


Nigba sise Re l’aye;
A nri pase Re lor’ okun,
O ngun igbi l’esin.

2. mp Ona Re enikan ko mo,


Awamaridi ni;
cr O pa ise ijinle mo,
Oba awon oba .

3. mp Ma beru mo , eyin mimo,


Orun to su be ni,
cr O kun fun anu yo rojo
Ibukun s’ori yin .

4. mp Mase da Oluwa l’ejo


Sugbon gbekele re le;
Gbati o ro pe o nibinu,
Cr Inu Re yo si O,

5. mf Ise Re fere ye wa na,


Y’o ma han siwaju;
Bi o tile koro loni
O mbo wa dun lola ,

6. Afoju ni alaigbagbo,
Ko mo ‘se Olorun ;
Olorun ni Olutumo ,
Y’o m’ona Re ye ni.
Amin.
824
12.12.7.&Ref.
Nitori Emi li Oluwa , Emi ko yipada. Mat.3:6

1. mf Olorun t’O mu Israel la okun ja ,


Ti O si gba won kuro li oko eru;
Ti o ro jo onje sile lati orun ,
f On ni mo ngbadura si.
Okan na loni , okan na loni,
Bakan na ni Olorun ti mo ngbadura si
La okun ja
Omo Re ni un o je , tori oro Re so
Pe, okan na ni Olorun Iyanu loni.

2. mf Olorun t’o gba Danel lowo kiniun,


T’o si yo awon meta n’nu ina leru,
Eni ti awon irawo ngba Tire .
f On ni mo ngbadura si.,

3. mf Olorun t’o f’oro Re d’afefe duro,


T’o si nso banuje oni d’ayo lola,
Eni ti O okuta boji kuro,
f On ni mo ngbadura si.

4. mf Olorun t’o wo itanna igbe l’aso,


Eni t;o mu omi san n’iyangbe ile
Ti O we elese mo ninu eri re,
f On ni mo ngbadura si.
Amin
825
11.11.11.7 &.Ref.
So fun awon omo Israei ki won ki o te siwaju. Esk.14:15

1. f Kristi Balogun wa niwaju ogun,


B’o ba ran wa ise ko ni beru;
Bi ohun t’o fe se ko tile ye wa.
Sibe ao tele titi.
ff Te siwaju si le leti na
Te siwaju si leri na
Te siwaju ko orin soke,
Pelu kristi , isegun daju

2. f Gbogbo ifeju esu ko le mi wa


Bi kristi je asa at apata wa;
Ao ma fi ide emi bi a ti nlo,
Ao ma tele titi

3. f E jeki a gbe asia wa s’oke,


Ibi ko le da ibiti o ba wa,
kristi, Balogun wa ti segun aye.
Ao ma tele titi.

4. f b’ogun na tile le ko ni pe pari


NIgbana ao dapo pel’awon mimo
Lati fi ayo ko orin isegun .
Bi a ba tele titi.
Amin.
826
8.8.6
Aba mi mbe lodo Olorun ti o nse igbala olotito li aya. OD.7:10.

1. mp Jesu mimo, ore airi,


Oluranlowo alaini,
N’nu ayipada aye ko mi
K’emi le ro mo O,

2. Ki nsa n;idapo mimo yi


Gba ohun t’o fe un o kun yi
B’okan mi b’eka ajara
Ba sa le ro mo O,

3. Okan mi t’are mu pupo


R’ibi isimi l’odo Re;
Ibukun ti de s’okan mi
Nitori t’o ro mo O.

4. mf B’aye d’ofo mo mi l’oju,


Ba gba ore at’ ara lo,
di Ni suru ati laibo ‘hun
L’emi o ro mo O,

5. mp Gbat’o k’ emi nikansoso,


Larin idamu aye yi
P Mo gb’ohun ife jeje na
Wipe, sa ro mo Mi’

6. cr B’are ba si fe saki,
f Ko si ewu fun okan na
Tori ba ro mo O,

7. mf Won ko beru’ runmi aye


Nitori Wo wa nitosi;
Won ko si gbon b’iku ba de
Tori won ro mo O,

8. Ire sa ni l’ohun gbogbo,


Ko s’eni le daya fo mi
Gba mo fi O s’ Olugbala,
Ti mo si ro mo O/.
Amin
827
L.M
Nitorina enikeni ti o ro pe duro ki o kiyesara ki o ma ba subu.Ikor 10:12

1. mp Oluwa , mo f’eru jewo


Pe , eni rere le subu,
Iyo le so adun re nu,
Ko ma si mo titi l;ae.

2. mf Ki oran mi mase ri be;


So okan mi po mo ra Re;
To mi sori oke lohun,
Koja l’afoniji fe,
Amin.
828
11.11.11.11.&Ref
Iya igba isisyi ko ye lati fi se akawe ogo ti a o fi han wa.Rom.8:18

1. cr Nigbati gbi aye yi ba nyi li o,


To si dabi enipe gbogbo re pin,
Ka ibukun re, siro won l’okokan,
Ise Oluwa yo je ‘yanu fun O,
mf Ka ‘bukun re, ka won l’okokan ,
Ka ‘bukun re, wo se Olorun ;
Ka’bukun re , ka won l’okokan,
Ka ‘bukun re, wa ri se t’ Olorun se.

2. mp Eru aniyan ha now kan re l’orun


Ise t’a pe o si ha soro fun o,
Ka ‘bukun re, Yemeji yo si fo lo,
mf Orin iyin ni yo si gb’enu re kan.

3. Gbat’o ba now awon oloro aye,


Ronu oro ti Jesu ti se leri;
Ka ibukun re, owo ko le ra won,
mf Ere re l’orun ati ‘le re l’oke.

4. mp Ninu gbogbo ayipada aye,


mf Mase foya, Olorun tobi julo;
f Ka ‘bukun re , awon angel’ yo to o
Won yo si ran o lowo titi d’opin.
Amin
829
L.M.& Ref
E ma yo ninu Oluwa nigbagbogbo fill 4:4

1. f E yo n’nu Oluwa , eyo;


Eyin t’okan se dede;
Eyin t’o ti yan Oluwa,
Le banuje at’ aro lo,
ff E yon’’nu Oluwa , e yo
E yo E yo
E yo E yo n;nu Oluwa e yo

2. cr E yo tori On l’Oluwa,
L’aye ati l’orun pelu;
Oro Re bor’ ohun gbogbo,
O l’agbara lati gbala.

3 cr Gbat’ e ba nja rere,


Ti ota fere bori yin;
mf Ogun Olorun t’e ko ri
Po ju awon ota yin lo.

4. mp B’okunkun tile yi o ka,


Pelu isundede gbogbo ,
Po gbekel’ Oluwa d’opin,

5 f E yo n’nu Oluwa , e yo,


E korin iyin Re kikan ;
Fi duru ati ohun ko
Aleluya l’ohun goro.
Amin
830
10.10.10.10.&.Ref
Ninu aye enyin o ni iponju; sugbon e tukuka; mo ti segun aye.Jn.16:33

1. pp I banuje po fun wa l’aye yi


Ekun m’oju wa tutu , o si su;
Mp Banuje at’ aro ko si l’ohun
cr Ni le na nibiti ko si odun
cr Ni ‘le na nibiti ko si odun.
Tabi ibanuje at’ ekun;
mf Ao gbe ‘ be l’alafia ayo wa yo po
Ni ‘le na nibiti ko si odun

2. cr Bi a sise t’ise wa si han,


A ni’gbagbo , ba ko tile r ‘eso
mf Sugbon Oluwa y’o asiri han
Ni le n nibiti ko si odun.

3. mf Sa tujuka li enu ise wa,


A gbagbe banuje at’ eru wa;
Tori bi nkan aye ba koja lo,
Ao gbe nibiti ko si odun.
Amin
831
9.9.9.8.&.Ref.
Ore-ofe mi to fun O.iikor.12:9

1. A won to gbekele Oluwa


Yio bori igbi idanwo
Nitori ileri yi daju,
‘Ore-ofe mi to fun O,
‘Ore-ofe mi to fun O,
Ore-ofe mi to fun O,
Ore-ofe ti ko l’egbe ;
Ore-ofe mi to fun O,

2. Manna lat’ orun li eyi je


Fun awon ero mimo l’ona
T, eru npa, to si nwa isimi,
‘Ore- ofe Mi to fun O’

3. Larin ire ije ti iye,


Bi are tile mu o subu;
Tun dide , ko si re siwaju;
Ore –ofe mi to fun O,

4. Idanwo ati iyemeji


At’ ewu kop le ba ileri yi mu;
‘Ore-ofe Mi to fun O,,
Amin
832
C.M.& Ref.
Oluwa yio ma to o nigbagbogbo Isa 58:11

1. mf Mase foya ohunkohun,


Olorun y’o to o
Ma gbe ibi ikoko Re
Olorun y’o to o.

2. f Olorun y’o to o;
Lojojumo l’ona gbogbo;
On y’O ma tohu re,
Olorun y’O to o;

2. cr Gbati okan re ba damu ,


mf Olorun y;O to o;
cr Gbat’ ewu ba wa l’ona re,
`mf Olorun y’o to o.

4. mf B’o ti wu k’ifdanwo po to,


Olorun y’o to o;
Simi, alare l’aya Re
Olorun y’o to o.
Amin
833
6.4.6.4.6.6 4
Fa mi lo bniile ti o teju.OD.143:10

1. mf Un osunmo’O, Olorun,
Un o sunmo O,
cr Bbo tile se ‘ ponju
L’O mu ni wa,
Sibe, orin mi je;
Un o sunmo’ O Olorun,
Un o sunmo O,

2. cr sNi ona ajo mi


B’ile ba su;
Bi okuta si je
Irori mi;
Sibe, n’nu ala mi,
Un o sunmo’ O , Olorun,
Un o sunmo’ O,

3. Nibe, jeki nr’ ona


To los’orun;
Gbogb’ ohun t’o fun mi
Nin’ anu Re,
Angel lati pe mi,
Sunmo O.

4. mf Nje gbati mo ji
Em’o yin O,
Un of’akeke mi se
Betel fun O,
cr Be , ninu osi mi,
Un o sunmo O Olorun,
Un o sunmo O

5. f Gba mba fi ayo lo


S’oke orun
To ga ju orun lo
S’oke giga;
Orin mi yio je
Un o sunmo O,
Un o sunmo O,
Amin
834
7.7.7.7.D
Ki a mase ri pe mi emi nsogo bikose ninu agbelebu Jesu kristi Oluwa wa.Gal 6:14

1. mp Mo mbo nib’ agbelbu,


Emi abosi julo;
Mo ka gbogbo nkan s’ofo
Lati ri gbala kikun.
cr Mo gbekele O ,Jesu
Odagutan kalfri,
di Mo fi rele teriba,
Gba mi, Jesu loni yi.

2. mf Mo gbekele leri Re ,
At’ agbara eje ni ,
mp Mo pon ara mi loju,
Mo nru agbelebu Re.

3. mf Jesu fi ayo kun mi,


O si mi di pipe;
Mo ni ilera pipe;
f Ogo ni f’Od’agutan.
Amin
835
C.M
Oluwa , ranti mi, Lk.23:42

1. mf I wo low’ Eni t’ire nsan


Mo gb’okan mi si O,
di N’ibanuje at’ise mi,
p Oluwa, ranti mi.

2. mp Gba nke rora l’okan mi


T’ese wo mi lorun,
cr Dari gbogbo ese ji mI,
P Ni ife, ranti ranti mi,

3. mp Gba danwo kikan yi mi ka


Ti ibi le mi ba,
cr Oluwa fun mi l’agbara,
p Fun rere, ranti mi,

4. mp Bi tiku at’ egan ba de


N’tori oruko Re
mf Un o yo s’egan un o ga tiju
B’Iwo ba ranti mi,

5. di Oluwa ‘gba iku ba de,


Em’o sa ku dandan,
P sK’eyi j’adura’gbehin mi;
Oluwa, ranti mi;
Amin.
836
S.M
Awa Sokun nigbati awa ranti Sion .OD.137:1

1. mf Jina s’ ile orun,


S’okan aya Baba,
Emi ‘bulkun wa, mo ndaku
Mu mi re bi simi

2. Mo fi duru mi ko,
S’ori igi willo;
Un o se korin ayo, gbati
Wo koi t’ahon mi se.

3. Emi mi nlos’ile ,
A mba le fo de ‘be;
Ayun mi Wo Sion
Gba mo ba ranti re

4. cr S’odo Re mo nt’ona
To kun isoro;
Gbawo ni un o koj’aginju aye ja,
Dele awon mimo.

5. mf Sunmo mi , Olorun ,
Wo ni mo gbekele,
Sin mi l’aginju aye ja
Ki ndele nikeyin.
Amin.
837
7.7.7.5.
Lati inu ibu wa li emi kepe O,Oluwa.OD.130:1

1. ‘Wo t’o ku ni Kalfari,


Won t’o mbebe f’f’elese,
Ran mi lowo nigb’aini;
cr Jesu, gbe mi.

2. mp Ninu ibanuje mi
At’ okan aigbagbo mi
P Ota l’ode ,eru n’nu
Gb’oju mi si O,

3. P Ota l’ode eru n’nu


Ko s’ire kan lowo mi;
Iwo l’o ngb’elese la
cr Mo sa to O wa,

4 . Awon miran d’ese pe


Won si ri igbala gba;
cr Won gbo ohun anu Re,
Mu mi gbo pelu.

5. mp Mo k’aniyan mi le O,
Mo si ngbadura si O,
Jesu yo mi n’nu rgbe;
Gba mi ki nma ku.

6. cr Gbati wahala ba de,


Nigbo agbara idanwo;
Ati lojo ikeyin .
Jesu, sunmo mi.
Amin.
838
C.M
Ongbe Olorun ngbe okan mi.OD42:2

1. mp Bi agbonrin ti nmi hele


S’ipaodo mi,
cr Beni okan mi mmi si O,
Iwo Olorun mi.

2. mp Orungbe Re ngbe okan mi


Olorun alaye;
P Nigbeyawo ni un o r’oju Re
Olorun Olanla?

3. p okan mi o se rewesi;
Gbekele Olorun
cr Eni ti y;o ekun re
D’orin ayo fun O,

4. mp Y’o ti pe ti, Olorun mi


Ti un o deni gbagbe;
T’ao ma ti sihin, sohun
B’eni ko ni’bugbe.

5. mp Okan mi o se rewesi;
cr Gbagbo wo op si ko
f Orin iyin s’Olorun re

6. Si Baba, omo at Emi,


Olorun ti a nsin
L’ogo ati ola ye fun
Titi ayeraye.
Amin
839
6.5.6.5.D
Mo ti gbadura fun o ki igbagbo re mase ye.Lk.22:32

1. mp Jesu nigba’ danwo


Gbadura fun mi;
Ki emi ma ba se O
Ki nsi saki lo
cr Gba mba s’iyemeji
Ko b’oju womi,
K’eru tab’ s’ isaju
Ma mu mi subu.

2. mp B’aye ba si nfa mi
Pelu adun re
T’ohun sura aye
Fe han mi l’emo,
Jo mu Getemani
di Wa s’iranti mi
pp tabi irora Re
L’oke Kalfari.

3. mp B’oba pon mi l’oju


Ninu ife Re
Da ibukun Re le
Ori ebo na;
Ki nf’ara mi fun O,
L’ori pepe Re;
B’ara ko ago na,
Igbagbo y’o mu.

4. p Gba mo ba nre ‘boji,


Sinu ekuru;
cr T;ogo orun si nko
L’eti bebe na;
mf Un ogbekel’ oto Re
Ni jakadi ‘ku
Oluwa gb’emi mi,
S’iye ailopin.
Amin
840
8.8.8.4
Ife Tire ni ki a se.Mat.26:42

1. mf Baba mi, gba mba nsako lo


Kuro l’ona Re laye yi.
Ko mi ki nle wi bayi pe;
P Se fe Tire..

2. mp B’ipinu mi laye ba buru,


Ko mi ki ngba, ki nmase kun;
Ki ngbadura,to ko mi, wipe;
‘Se fe Tire’

3. mp B’o ku emi nikansoso,


Ti ara on ore ko si;
N’iteriba un o ma wipe;
‘Se fe Tire’

4. mp B’o fe gba ohun owo mi,


Ohun to se owon fun mi,
Un ofi fun O se Tire ni,
‘Se fe Tire’

5. mp Sa I Emi Re tu mi n’nu,
Ki On ko si ma ba mi gbe,
Eyit’ o ku od’ owo RE,
‘Se fe Tire’

6. Tun ‘ fe mi se lojojumo
K’ osi mu ohun na kuro
Ti ko je kemi le wipe
‘Se fe Tire’

7. p Gbat’emi mi ba pin l’aye


cr N’ilu to daraju aye
f L’emi o ma korin na titi
‘Se fe Tire;
Amin
841
6.4.6.4 6.6.4.
Alejo niile alejo.Eks.2:22

1. mp Nihin mo j’alejo.
Orun nile;
Atipo nimo nse,
Orun nile;
Ewu on ‘banuje
Wa yi mi kakiri,
cr Orunni ilu mi,
Orun ni ile.

2. mf B’iji ba tile nja,


Orun nile;
di Kukuru l’ajo mi,
Orun n’ile
Iji lile ti nja,
cr Fe rekoja lo na,
Un o sa dele dandan,
Orunn’ile;

3. L’odo Olugbala,
Orun n’ile;
cr Ao se mi logo,
Orun n’ile;
P Nib’awon mimo wa
L’ehin ‘rin-ajo won,
Ti won ni ‘simi won,
cr Nibe n’ile

4. mf Nje nki o kun n’’tori


Orun n’ile;
Ohun to wu ki nri
Orun n’ile.
cr Un o sa duro danadan
L’orun Oluwa mi;
ff Orun ni ilu mi,
Orun n’ile
Amin.
842
8.8.8
Oluwa mbe fun mi, emi ki yio beru ; kili eniyan le se si mi? OD.118:6

1. f Un o se foya ojo ibi?


Tabi ki nma beru ota mi,

2. Bo ti wu k’ija gbona to’


Ka mase gbo pe emi nsa;
Tori Jesu l’apata mi

3. P Nko m’ohun to le de, nko mo


cr Nko m’ohun o le de, nko mo
Bi nki o ti se wa l’aini
cr Jesu l’O mo ;Y’O si pese

4. p Bi mo kun f’ese at osi ,


cr Mo le sunmo ite-anu,
Tori Jesu l’ododo mi;

5. p B’adura mi ko nilari,
cr Sibe reti mi ki o ye ;
Tori Jesu mbebe loke

6. f Aye at’ esau nde si mi;


ff Sugbon Olorun wa fun mi;
Jesu l’ohun gbogbo fun mi.
Amin.
843
9.7.9.7.&.Ref
Emi wa pelu yin nigbagbogbo ,
Titi o fi de oipn aye. Mat.28:20

1. Orin kan wa ninu okan mi,


Jesu so jeje wipe;
mp Mase beru , mo wa pelu re
Ninu gbi aye gbogbo’
f Jesu , Jesu Jesu,
Ti o dun julo,
Gba gbogbo ife mi,
O si nm,u korin lo.

2. p Ese ti ba ‘gbe aye mi je,


Irora kun okan mi,
mf Jesu ti mu gbogbo ife mi
O si nmu mi nin orun

3. Fun ipese ore-ofe Re,


Fun kun okan mi;
Fun oju rere Re , gba gbogbo
f Ni mo se nkorin kikan.

4. Bi mo tile nla omi koja ,


To wahala wa lona;
Ti ona ko si igbadun,
On sa wa ni iwaju.

5. f Ni aipe titi, Y’O to mi wa


Lat’ orun giga l’oke;
Un o fo ba lo so orun mimo,
Un oma ba joba l’oke.
Amin.
844
8.78.7.
Awon eni irapada Oluwa yio pada, won o si wa si Sion ti awon ti orin .Isa51:11

1. mp Ninu oru ibanuje


L’awon rgbe ero nrin;
mf Won nkorin reti at’ ayo,
Won nlo sile ileri.

2. mp Niwaju wa n’nu okunkun


Ni imole didan ntan ;
mf Ara ngba ara won lowo
Won nrin lo li aifoya.

3. mf Okan ni iro ajo wa,


Ti ntan s’ara eniyan Re;
Ti nle gbogbo eru jina,
`Tintan yi ona wa ka.

4. Okan ni iro ajo wa,


Okan ni igbagbo wa,
Okan l’Eni ta gbekele,
Okan ni ireti wa.

5. mf Okan l’orin t’egberin nko,


Bi lati okan kan wa;
Okan n’ija, okan wa;
Okan ni irin orun.

6. Okan ni inu didun wa,


L’bute ainipekun;
Nibiti Baba wa orun
Y’o ma joba titi lae.

7. cr Nje ka ma nso, eyin ara


T’awa ti agbelebu,
E jeka ru, ka si ijya
Tit’ao fi ri Simi.

8. f Ajinder nla fere de na,


Boji fere si sile ;
Gbogbo okun yo si tuka
Gbogbo okun yo si tan.
Amin
845
L.M
Ma ja ogun rere ; ma ni igbagbo, Itim 1:18-19

1. mf Ja ija rere t’igbagbo,


Ja nipa agbara kristi;
Di iye ainipekun mu,
Ayo at’ ade re titi,

2. mf Ma sa ije t’iye,
Gboju soke fun gbogb’ ainiyin
cr Kristri li ona Iye re,
Kristi li opin ere re,

3. Ma s’aniyan ohunkohun,
Y’o pese fun gbogb’aini yin
cr Eni gbagbo ki yo damu.

4. mf O mbe nitosi, ma beru;


Eni ti ki yi pada ni;
cr Sa gbagbo , si gbeke re le
Y’o je ohun gbogbo fun O,
Amin
846
7.6.7.6.D
Bi igi opoto ki yio tile tanna, Sugbon emi o ma
Yo ninu Oluwa Heb 3:17-18

1. mf Gba , Mole yo l’ojiji


Si Kristian ti nkorin;
Oluwa ni O ndide
Pelu ‘mularada;
Gbati irora ndinku
On a tun fun okan
On a tun okan sansan
Lati mu l’araya.

2. cr Pelu isaro didun ,


A ranti Ife Re;
mf Igabala nla n’nu Jesu,
Otun ni titi lae;
Eyi le ‘banuje lo;
Onmu okan wa yo,
Ba ko tile mo ola,
A nireti didun,

3. cr Ohun to wu ko mu wa,
On y’O mu wa laja;
Eni daso bo koko,
Yo da bo eniyan Re,
Labe awosanma Re,
Ko s’eda ti ki bo,
Eni mbo awon Re l’onje,

4. cr B’ajara tab’ opoto


Ko tile so eso,
Bi gbogbo ko tile ro,
T’agbo eran segbe
mf Olorun mbe bakanna;
f Un o korin iyin Re;
Bi mo ti ngbeke mi le,
Ayo mi yo ma po.
Amin
847
L.M
Loto o ti ru ibinuje wa, o si gbe ikanu wa lo.
Isa 53:4

1. cr Gbogbo iya mi n’Iwo mo,


Iwo t’;a danwo bi emi;’
mp Wo ‘ kanu mi, wo kanu Re,
Jesu , K’O ranti kalfari.

2. O ko ha mo si eda
Kristi ha d’ekun anu se
P O ko ha mo ‘banuje mi
O ko ha pin n’nu rora mi.

3. Nko ha ti gbo, nko ha ti mo


Pe , Oluwa ayraye
T’orun at’ aye jewo Re
A ma mu ileri Re se

4. mf Emi mo pe ‘ Wo ki o gan
A ko bere se igbala;
Mo mo pe Orun ododo
Y’o la pelu ‘mularada .
Amin.
848
8.8.8.D
Abo mi mbe lodo Olorun ti O nse igbala olotioto li aiya. OD.7:10

1. cr F’ona re l’Oluwa lowo,


Si gbekele f’ohun gbogbo;
Lojo ibi, iwo yo ri
Pe On nikan L’O to o gba’
mf Eni gbekele Olorun
Duro sinsin lor’apata.

2. mf Iwo saf’okan re bale


Si ma duro n’nu ireti,
F’itelorun gb’ohunkohun
T’ore on ife Re mu wa
Ma foya , gbogbo aini wa
L’Olorun wa mo laikukan.

3. Mase fi ona Re sile ,


Sa ipa re tokan-tokan ;
Ma gbekele ileri Re
Titi gbogbo won fi se;
cr Baba ko ko enikan ri
Ti o gbekel’ E nitoto.
Amin
849
8.8.8.D
Mo ti pe o li oruko re; ti emi ni iwo . Isa 43:1

1. mf Mase beru, won okan mi;


Elwda mi ni nma foya;
Oluwa pe mi l’oruko;
O ndabobo, ko si jinna,
Eje Re ti s’ etu fun mi,
O nfe , o si nto mi sibe.

2. cr Gba mo nkoja larin in\bu,


Mof’ igbagbo toro ranwo,
Igbi si duro l’okere,
Won bi kuro li ori mi
mf Emi ko beru ipa won;
Ko si ewu, Olorun mbe.

3. Mo yi oju igbagbo larin s’


Mo ntesaiwaju larin m na
Ina gbagbe lati jo mi ,
Owo ina njo yi mi ka;
Mo jewo agbar’ ami na
Mo ke pe ‘Temi ni Jesu’

4. cr Olugbala duro ti mi ;
Dabobo mi nigba danwo
P mi mo ni ikawo Re ;
F; agbara Gbala han n’nu mi
Ki apa le abo mi,
Ko s’ohun le ja mi kuro,

5. B’o si ti pe mi pe ki nwa
‘Wo ‘ Olore ti ngba ni la,
Un o rin lori okun ti nja
Igboi yo gbe ese mi ro
Nki yo beru isan na ,
Bi o ti wu ki o le to .

6. mp Gbat’okunkun b’oju Orun


T’igbi , banuje yi mi ka ,
T;iji ibinu ru soke
To fere bori okan mi
mf Emi mi yo ri dake je,
pp Yo gb’ohun jeje pe, ‘Simi
7 f Bi mo wa n’nu eru ponju,
Laisewu un o sete iku;
B;ese doju ija ko mi
Ti esu gbe ogun ija ti mi
B’igbo Mose, un o ma gberu,
Ina ki o pa mi lara.
Amin
850
15.7.15.7.&.Ref.
Nitoriti O ni ife si Mi , nitorina li Emi O se gba OD.91;14

1. cr N’nu n ijakadi aye re a ki yo le segun re,


B’okan re b’Oluwa rin;
Mf Iwo yo ma segun nso titi iwo yo fi bade
B’okan re b’Oluwa rin .
mf B’okan re b’Oluwa rin,
B’ okan re b’Oluwa rin
Iwo jki yo mo subu,
f Sugbon isegun pipe
B’okan reb/Oluwa rin

2. Awon odo idanwo nla ki yo le bo o mole,


B’okan re b’Oluwa rin ,
Oko re ki yo ri sinu igbi idamu aye,
B’okan reb’Oluwa rin.

3. mf Itelorun at’ yo mole s’ona re


B’okan re b’Oluwa rin;
Igboya ninu idanwo isegun ninu ija;
Gb’okan re b’Oluwa rin.
Amin
851
8.8.8.6.&.Ref.
Iya igba isisiyi ko ye lati akawe ogo ti a o fi han ninu wa.Rom 8:18

1. mp Eru , aniyan ndamu re


Isoro nk’ are ba o bi?
mf Onirobinuje, y’ ayo
Ife Krist’ to fun o,
. cr B’ona su , gbekele fe Re
Y’o fi iyin kun okan re,
Korin ni gbogbo lojojo,
Ife Krist’ to fun o,

2.. mp Wo kuna oro aye bi.


cr Ka si ere wo Kalfari,
Ife Krist’ to fun o,
L’orun ni isura re wa,
Ife Krist’ to fun o,

3. Wo ko gba iyi laye bi?


Sibe , Baba nse toju re,
Fun o li omo Re se ku,
Ife Kruist’ to fun o..
Amin
852
10.10.10.7.&.Ref
E wa sodo mi gbogbo enyin ti a di eru wuwo le lori .Emi o fi isimi fun yin. Mat.11:28

1. cr Bi eru ese ba nw o o lorun,


mf Ore kan mbe to nm’ imi alafia
T’o si nmu k’ailera n’isegun
Jesu l’Ore t’iwo nfe,
mf Jesu l’Ore t’ iwo nfe ara mi
Jesu ni Ore toto toto
Fi Jesu s’ore si gbekele re l’E,
N’tori Jesu l’Ore toto.

2. Ninu irin ajo re li aye,


On li Ore to le ran o lowo ;
L’ayo l’okan le Jesu,
Jesu l’Ore t’iwo nfe.

3. mp Gbati danwo ba okan re jagun ,


mf Or’-ofe Re bori gbogbo ibi;
Gbekele Ore ti ko le da o.
Jesu l’Ore t’iwo nfe.

4. mp Gbati kuku okunkun yi o ka,


Ni igbekele ore-ofe Re;
mf Ore.nla yi yo mu imole wa;
Jesu l’Ore t’iwo nfe.
Amin
853
8.7.10.7.D.&.Ref.

1. mf Mole kan mbe leyin ‘kuku,


Gbogb’ egun lo n’itanna,
Nigbati Oluwa wa nitosi;
Okan wa k’o yo sfo mo,
f Mole ayo orun kan wa
Bi mole miran kuna,
Nigbat’ a mo ife Oba orun,
Ife ti yo bori lae.
ff Aleluya Aleluya
O si ti dariji wa
Alafia Aleluya
Alafia ngbe n’nu wa
A layo n’nu Olugbala ,
A si nyo ninu fe Re
Aleluya ,Aleluya
S’ Oluwa Olubukun.

2. cr Leti Olorun lao fi bo


Ogun ‘banuje mole;
Oro Re daju o wa titi lae.
mf Reti ayo lo ntan ka ;
A si mo p’ojo ola yo
Dan ju mole osan lo.
f B’imole de, okunkun parada
Beni yo wa titi lae

3. cr Ki mole orun dari wa .


Ka f’ayo rin l’ona na
Ki erin wa je ti ore-ofe
Fun awon alailera;;
Ao wa fun Jesu nikanso
Ayo Re l’;agbara wa,
Ti ao fi pade leyin aye yi,
Amin
854
8.8.8.6 &.Ref
Nitori ti oun nse itoju nyin, I pet5:7

1. mf N’nu gbogbo ‘danwo ti mba mi


Larin idamu aye yi;
cr Iro kan nmu mu mi dun
mf Baba ngbero fun mi,
f Baba ngbero fun mi.
Baba ngbero fun mi
Eese ti un o tun ma beru
Gbat O ngbero fun mi.

2. mp Gbat’ igbi aniyan ba de


Lati teri okan mi ba;
cr Sibe mo ranti ohun kan
mf Pe . Wo ngbero fun mi.

3. cr Ohunkohun to wu ko de;
Ayo tabi ibanuje;
Ohun kan sa da mi loju
mf Pe; Wo ngbero fun mi
Amin
855
14.14.14..10.&.Ref
Beulah nitori inu Oluwa dun si o. Isa.62:4

1. mp Mo n gburo iji ti li ona jinjin rere


Mo si mo pe ese ndan ni wo ni aye yi
mf Iyemeji at’ eru ko le pa mi lara mo
Wonyi ko le mu mi kuna Beulah.
f Mo gbe ni ori oke . gbogbo danwo si fo lo
Yin Krist;
Mo nmu n’ibi orisun ti kole gbe titi,
Mo nje onje na t’ise Manna lati oke orun wa
Nitori mo ngbe nile benile Beulah.

2. mf Mo jinna s’ibiti iyemeji ndamu aye.


Nibiti ota ngbogun ti omo eniyan;
Mo ngbe lailewu li ebute oro Olorun ,
Ko s’ewu ori mo ngbe ni Beulah.

3. mf Bbo ti wu ki iji to , eru ko le ba mi,


Owo Olorun li abo to daju fun mi
Nibe l’orun nran titi, ko si ifoya fun mi,
Ko s’ewu tori mo ngbe ni Beulah.

4. p Gbati mo now ‘se Olorun okan mi wariri,


cr Mo ngb’ohun ife Re on nseto fun mi,
Emi Re Nfihan mi pe igbala didun l’eyi
mf Un o fi ayo gbe ni ile Beulah.
Amin.
856
11.11.11.15
Okan wa duro de Oluwa On ni iranlowo wa ati asa wa OD 33:20

1. mf Olorun emi wa at’ igbala wa


Mole okunkun on reti gbogb’ aye,
Gbo , ki O si gba ebe ijo Re yi,
Olodunmare,

2 mp Wo bi ibinu ti yi Ijo Re Ka,


Wo b’awon ota Rre ti n’asia won
Bi won si ti nju oko olotoro won,
Wo le pa wa moi,

3. f Wo le se ranwo b’iranwo aye ye,


Wo le gba ni low. Ese ti npa ni run,
P Iku at’ esu ko le bor’ ijo Re;
F’;alafia fun wa.

4. Fun wa lowo titi ota o paehinda


Fun won l’oto Re k’a le dariji won
K’a r’alafia l’aye, leyin ija wa;
Alafia L’Orun.
Amin
857
7.6.7.6.&.Ref.
Awon ti o gbekele Oluwa yio da bi oke Sion OD.125:1
.
1. mf Gbekele, Onigbagbo;
Bi ja na tile pe,
Iwo ni t’o dsa segun,
Baba y’o ja fun o,
Sa gbekele
B’okunkun tle su
Sa gbekele
Ile fere mo na

2. mf Gbekele larin ewu,


Danwo nla wa n’osi;
Lain wahala aye
Y’o ma s’amona re

3. mf Jesu to lati gba wa,


Ore toto l’O je;
Gbekele, Onigbagbo;
Sa gbekele,d’opin.
Amin
858
L.M
Olorun li abo wa ati agbara, OD.46:1

. 1. mf Olorun l’abo eni Re ,


N’igba iji iponju de;
K’awa to se aroye wa
Sa wo, oun ti iranwo Re.

2. Bi a si oke nla n’idi,


Ti a ri s’isale ibu;
T’isele mi aye ayo papa,
Igbagbo wa ki o yese.

3. f B’o ti wu ki ‘gbi na le to,


Ti gbogbo orile-ede
Si nfoya riru omi na
Okan wa mbe l’alafia.

4. Odo kan wa ti sisan re


Ninu n’u illu Olorun dun;
Iye, ife ati ayo
Nsan larin re, o mb’ omi rin.

5. Odo na li oro iye


Ti nsakoso ipaya wa
Leri Re nmu alafia wa
O nf’ilera f’okan are

6. Sion ngbadun fe Oba re;


O bo lowo ewukwu
A ko lori otito RE
Ipile re ko le ye lae
Amin
859
8.7.9.7.8.6 10.7.&.Ref
O si ji, o ba afefe na wi.Mk4:39

1. mp Oluwa, iji nj kikan,


Igbi omi nru s’oke;
Oju orun pelu su dudu,
P Renlowo ko si n’tosi;
cr Wo ko bere, bi a segbe
Wo s’ha se le sun
Gbati seju kokan d’eru ba wa
L’e omi n’iboji wa
mf Afefe at’igbi y’o se fw mi;
p Dake je;
mp Ibase binu riru okun,
Ibase esu tabi Ohunkohun,
f Ko si omi t’o ri oko na,
ff Ti Oluwa O run at’aye wa;
cr Won y’o f’ inudidun se fe mi,
p Dake je.

2. mp Oluwa , pel’ edun emi,


Mo teriba n’ironu;
pp Inu okan mi ko ni simi;
A ji k’O gba mi , mo segbe;
Igbi ese on binuje
Bo okan mi mole;
cr Duro Olurapafda mi;
Ma fi mi sile mo;
f Pel’ayo un o d’ebute ibukun
Un o simi l’ebute na
Amin.
860
D.C.M
Oluwa gbo Oluwa dariji.Dan9:19

1. mf Gb’adura wa , Oba aye


Gbati a wole fun o;
Gbogbo wa nkigbe n’irele,
di A mbebe fun anu;
Tiwa l’ebi , Tire l’anu,
Mase le wa pada;
Sugbon gb’ gbe wa n’;ite Rre
Ran ebe wa lowo.

2. p Ese awon baba ewa po,


Tiwa ko si kere
Sugbon lati irandiran
L’o ti f’ore Re han
Nigba ewu, b’omi jija
Yi ilu wa yi ka ,
Iwo l’a wo si ke pe.
K’a ma ri ranwo Re

3. p L’ohun okan gbogbo wa wole


L’abe ibawi Re
Gbogbo wa njewo ese wa,
A ngb’awa fun aini wa
F’oju anu wo aini wa
Bi a ti nke pe O,
Fi idajo Re bu wa wi,
Da wa si l’anu r.
Amin.
861
7.7.7.5
Gbo , Oluwa nigbati mo ba fi ohun mi pe; sanu fun mi.OD 27:7

1. cr Olorun , Olori –ofe,


Gbat’a nfi rele wa O,
mp B’ojuwo ‘le lat’ orun;
Gbo . si ngba wa la.

2. Gba ba pejo n’ile Re,


T ‘a nso ohun t’o ndun wa.
T’a nbebe n;ite anu,
cr Baba, gba wa la

3. Gba fe Re kun okan wa


Ti a nfe se fe Tire ,
T’a now oke mimo Re,
cr Baba , gba wa la,

4. mp B’a ba sako jinna lo,


p T’ ife wa tutu si O,
cr F’oju anu Re wo wa;
Jo dariji wa

5. mp Gbati banuje ba de
Pelu idamu aye
cr F’alafia f’okan wa;
Jesu, gba wa la,

6. cr Ohun wu k’edun wa je,


Gbati’ a ngbadura si O,
F’opin si ipaya wa;
Gbo, si ba wa la
Amin
862
C.M
Dide , Oluwa , Olorun gbe owo re soke ; mase gbagbe oluponju;OD.10:12

1. cr Olorun , ranwo eni Re.


Reti wa n’igba ‘bi,
A gba ‘wo Eni Airi gbo,
mp Awa nwa O sibe,

2. cr Ese ti awon elese,


Nfoudi ipa Re,
di Ti won si nhale b’ enipe
Wo ko ri ese won?

3. Oluwa , dide k’o gba wa;


A m’oran wa t’O wa
F’ododo at’ ipa joba,
‘Wo nikan li Oba .

4. mf Iwo mo gbogbo ife wa’


Ranwo Re wa n’tosi
Pese okan wa f’adura,
Si gba adura wa,
Amin
863
6.6.6.6.&.Ref.
Iranlowo wa mbe li oruko Oluwa ti O da orun on aye.OD.124:8

1. mf Baba, Wo l’a to wa
F’anu at’or-ofe;
Jowo gbo igbe wa ,
Ma m’oju Re kuro ;
cr Baba , na wo agbara Re,
Ki o si bukun ile wa.

2. f Dide , Oluwa wa
Jowo f’oruko Re,
Le gbogbo ese lo
Kuro ni ile wa.

3. Ro ojo ‘bukun Re
Siwa lopolopo;
K’a le ma gbe O ga,
K’a ma yin O titi.

4. Fi ogbon Re orun
F’awon olori wa;
Se won ni iranse Re
Ki won fe ododo.

5. mf Ru ijo Re soke
Pelu ina ife;
Tun dapo si okan
F’oto at’ iye fun.

6 cr Fi ore-ofe Re
F’awon alufa Re
Se won l’ojise Re
Ninu iwa –mimo.

7.. cr Je k’a fe ile Re


K’a ya ‘jo Re soto,
Lati josin fun O,

8. mf F’alafia fun wa;


Le ota wa jinna,
K’a ma f’afojudi
Dese s’ola-nla Re
9. B’a ti agidi to,
Ko s’Olorun miran
Ti ao sin lahin re.
Amin
864
11.11.7.7.7.11.4.
.Oluwa , Olorun wa Olodunmare njoba. If 19:6

1. mf Iwo okan t’eru npa , Jesu njoba’


Woke, n’omije re nu re nu, Jesu njoba’
B’ogun ota tile po,
Won ki yio le bori;
Gbekele Jesu ki y’o ko o sile.
f Jesu njoba’

2. f K’okiki otioto na ‘Jesu njoba’


Eyin mimo, gberin na ‘Jesu njoba’
Sion, ji la ojumo mo,
Wo bo l’oluso nke pe. Jesu njoba’
‘Jesu njoba’

3. f Ji, Ijo Kristi l’aye ‘Jesu njoba’


Gbe hamora gboya wo ‘Jesu njoba’
Laipe on’ y’o sokale
Lati gba o ni Ttire;
Ao si gbe ese mi ‘Jesu njoba’
‘Jesu njoba’
Amin
865
L.M
Jakobu yio ha se le dide? Amo 7:2

1. mf Tani o gbe Jakob’ dide’


Ore Jkob’ ko po;
Eyi t’o je yanu ni pe,
Imo won ko sokan .

2. mf Tani o gbe Jakob’ dide’


Ota Jakob’ n’ipa;
f Mo r’auo’ segun l’oju won ,
p Won ni’ ‘o pari fun ‘

3. mf Tani o gbe Jakob’dide’


A ha r’eni le wi;
P Eka t’o ro nibule yi.
cr O ha tun le ye mo/

4. mf Oluwa mi, ise Rre ni’


Ko s’eni t’o se ;
P Se b’iri Jakobu,
f On yio si tun ye.
Amin.
866
8.8.8.D
Nibo ni iwo wa? Gen.3:9

1. mf Nigbat’ idanwo yi mi ka,


p Ti damu aye yi mi ka;
T’ota f’ara han bi Ore
Lati wa iparun fun mi ;
f Oluwa jo ma s’ aipe mi
Bo ti pe Adam nin ogba
di Pe, Nibo lo wa’ else
Ki nle ninu ebi na.

2. f Nigbat’ Esu n’nu tanje re


Gbe mi gori oke aye,
T’o ni ki nteriba fun on
K’ohun aye le je temi

3 f Gbat’ ogo aye ba fe fi


Tulasi mu mi rufin Re
T;o duro gangan lehin mi;
Ni ileri pe ko si nkan

4. Nigbati igbekele mi
Di t’ogun ati t’orisa
T’o ede di adura mi
T’o ofo di ajisa mi

5. Nigbati mo fe lati rin


L’adamo at’ ife ‘nu mi
T’okan mi nse hilahilo,
Ti nko gbona ti nko tutu

6. p N’igba mo sonu bi aja


Laigbo ifere ode mo,
Ti nko nireti ipada.
Ti mo npa fo ninu ese

7. Nigbati ko s’ alabaro’
Ti Olutunu si jina;
P T’ibanuje si iji lile
cr Te ori ma ba ironu.
Amin.
867
8.7.8.7.
Wa soso mi, Isa 55:3

1. mf Emi o lo s’odo Jesu,


Eni npe mi pe ki’ m’wa,
Eni t’O se Olugbala
Fun else bi temi.

2. mf Emi o lo sodo Jesu,


mp Irira at’ ibinu,
cr Ika at’ ise t’o buru,
T’eyan nse, On ko la?
3. mf Eni o lo sodo Jesu,
O dun mo mi ki nse be;
Tal’o fe mi bi I Jesu ,
Eni ti O gba ni la,

4. Emi p lo sodo Jesu,


Jesu t’o se Ore wa
Anu wa ninu Re pupo,
Fun else bi emi
Amin
868
C.M
Mase je ki awon ti nwa O ki o damu.OD.69:6

1. mf W o bi awa eniyan Re
p Ti wole l’ese Re
Olorun kiki anu Re
Ni igbekele wa.

2. f Idajo t’o ba ni leru,


Nfi agbara Re hn;
Sibe, anu da lu wa si;
Awa si ngbadura.

3. mf Olorun, o se da wa si,
Awa alaimore?
Jo, je k;agbo ikilo Re,
Nigbati anu wa.

4. Iwa buburu ti po to,


Yika ile wa yi
Bukun ile wa lo to yi
Wo b’o ti buru to

5. f Oluwa , fi ore –ofe


Yi wa l’okan pada
Ki a le gba oro Rre gbo,
K’a si wa oju Re.
Amin
869
L.M
Eni ti o si gbekele Oluwa, ibukun ni fun.Owe 16:20

1. f Ojo nla l’ojo ti mo yan


Olugbala l’Olorun mi;
O ye ki okan mi ma yo,
K’osi ro ihan na kale.
f Ojo nla l’ojo na
p Ti Jesu we ese mi nu;
O ko mi ki nma gbadura
Ki nma , sora, ki nsi ma yo,
Ojo nla l’ojo na
Ti Jesu we ese mi nu.

2. mf Ise igbala pari na,


mo di t’Oluwa mi lori,
On l’o pe mi, ti mo si Je,
ff Mo f’ayo ipe mimo na .

3. Eje momi yi ni mo je
F’eni to ye lati fran;
Je k’orin didun kun ‘ le Re
Nigba mo ba nlo sin nibe.

4. Simi, aduro okan mi,


Simi le Jesu Oluwa;
Tani le wipe aye dun.
Ju odo awon angeli.

5. Wo orun t;o ngbo eje mi,


Y’o ma tun gbo lojojumo,
P Tit’ ojo t’emi mi y’o pin
Ni un o ma m’eje mi na se.
Amin
870
8.7.8.7.7.&.Ref
Nitori ko di ini fun awon ti o beru Re OD.34:9

1. mp Oro aye le di ‘baje,


Ohun ti mo fe le bo,
cr Itura mbe l’odo Jesu
Ki l’ohun ti mo tun nfe.
Ki l’ohun ti mo tun nfe;
mf Mo ni Krist’ ko s’aini mo ,
Owo Re ntu ebun ka
Un o ma korin yin titi
Mo ni Krist’ ko s’ aini mo.

2. mp Bi ayo aye ba kuna,


Lati mu inu mi dun;
mf Jesu ti ru ‘ banuje mi,
N’nu Re mo r’ ohun gbogbo ,
N’nu Re mo r’ ohun gbogbo,.

3. mf Sinu ibu ibukun Re,


Jesu si lekun sile.
f Ninu Re mo r’ ohun gbogbo,
Aini ko si fun mi mo,
Aini ko si fun mi mo,
Amin.
871
7.6.7.67.6 D
Olorun ayeraye ni ibugbe Rre.Deut 33:27

1. mp Laifoya l’apa Jesu,


Laifoya l’aya Re
cr Labe ojij’ ife Re
L’okan mi o simi ,
P Gbo ohun angeli ni,
Orin won d’eti mi
cr Lati papa ogo wa
Lati okun Jaspa;
mf L’aifoya l’aya Jesu
L’aifoya l’aya Re;
L’abe ojij’ ife Re
L’okan mi o simi.

2. mp L’aifoya l’apa Jesu,


Mo bo low’ aniyan ;
Mo bo lowo idanwo,
Ese ko nipa mo;
Mo bi lowo banuje,
Mo bo lowo eru;
cr Laifoya l’apa Jesu
Laifoya l’aya Re
L’abe ojij’ ife Re
L’okan mi o simi.

3. mp Jesui, abo okan mi,


Jesu ti ku fun mi;
f L’emi o gbekele;
Nihin l’emi o duro
mp Tit’ oru l’apa Jesu,
Ni un o fi ri mole
mf Laifoya l’apa Jesu,
Laifoya l’aya Re ,
L’abe ojij’ ife Re
L’okan mi o simi.
Amin
872
S.M
Oluwa ,li Iwo ni mo gbekele mi leOD.31:1

1. mf Mo f’emi mi s’abe
Itoju Re , Jesu ;
Iwo ki y’o ko mi sule,
Wo l’Olorun ife.

2. f Wo ni mo gbekele,
Wo ni mo f’ara ti
Rere at’ otito ni O,
Eyi t’o se lo to.

3. Ohun t’o wu ko de,


Ife Re ni nwon n’se
P Mo f’ or pamo s’aya Re;
Nko foya iji yi,

4. f B’ibi tab’ ire de,


Y’o sa dara fun mi;
Ki nsa ni O l’ohun gbogbo
Ohun gbogbo n’nu Re
Amin
873
C.M
Oruko Re tabi ikunra ti a tu jade, O .Sol.1:3

1. f B’oruko Jesu ti dun to


L’eti onigbagbo ;
O tan ‘banuje on ogbe,
O le eru re lo.

2. mf O wo okan t’o gb’ ogbe , san,


O mu aya bale ;
Manna ni fun okan ebi,
Isimi f’alare.

3. f S apata ti mo kole le,


Ibi isadi mi
Ile isura mi t’o kun
F’opo ore-ofe.

4. cr Jesu, oko mi , ore mi,


Woli mi Oba mi.
Alufa ,Oba mi,
Gba orin iyin mi.

5. p Ailera l’agbara nu mi;


Tutu si l’ero mi
Gba mo ba ’ri O ti ri
Un o yin O b’o ti ye,

6. f Tit’ igba na, ni ohun mi


di Y’o ma royin , fe RE;
di Nigba iku k’oruko Re
p F’itura f’okan mi.
Amin
874
13.11.13.11.13.11.14.11.&.Ref
Emi ni itanna lili awon afonifoji .O Sol.2:1

1. mf Mo ti ni Jesu l’ore O jj’ohun gbogbo fun mi;


On nikan l’Arewa ti okan mi fe;
On n’itanna ipado , on ni Enikan na
T’o le we mi nu kuro n’nu ese mi,
cr Olutunu mi l’O je n’nu gbogbo wahala
On ni ki aniyan mi l’oun lori,
f On ni itanna ipado , Irawo Owuro,
On nikan l’Arewa ti okan ni fe,
cr Olutunu mi l’O je n’nu gbobogbo wahala
On ni ki nk’ aniyan mi l’o n lori;
f On itanna ipado, Irawo owuro,
In nikan l’Arewa ti okan mi fe.
2. cr O gbe gbogbo .banuje at’ irora mi ru,
O j’odi agbara mi n’igba ‘danwo ;
Tori Rek’ohun gbogbo ti mo ti fe sile,
O si f’ agbara Regbe okan mi ro;
mp Bi aye tile ko mi ti satani dan mi wo ,
Jesu yo mu d’opin irin mi;
mf Onitanna ipado, irawo owuro,
On nikan l’Arewa ti okan mi fe.

3. mf On ki y’o fi sile , be k’y’o ko mi nihin,


Niwon ti nba fi gbagbo p’ofin Re mo;
Oj’ odi na yi ma ka nki y’o berukeru,
Y;o fi manna Re b’okan mi t;ebi npa,
Ggba mba d’ade n’ikeyin un o r’oju bukun Re
Ti adun Re y;o ma san titi lae
f On nikan l’Arewa ti okan mi fe.
Amin
875
10.8.10.8&.Ref
E wa sodo mi, gbogbo enyin ti nsise,ti a si di eru wiwo le lori, Emi o si fi isimi fun nyin,
Mat 11:28

1. mp B’eru ese re ba now o lorun,


Pe Jesu wole okan re;
B’o nd’aniyan isoji okan re,
mf Pe Jesu wole okan re,
cr Le yemeji re sonu,
Ba Oluwa re sonu ,
di Si okan re paya fun,
Pe Jesu wole okan re

2. mf Bi o ba nwa iwenumo kiri,


Pe Jesu wole okan re,
Omi wenumo ko jina si O
Pe Jesu wole okan re.

3. p B’igbi wahala ba ngba o kiri


Pe Jesu wole okan re;
cr B’afo ba wa ti aye ko le di,
Pe wole okan re,

4. p Bi ore t’o gbekele ba da o


Pe Jesu wole okan re,
mf On nikan ni Olubanidaro,
Pe Jesu wole okan re.

5. mf B’o nfe korin awon Olubukun


Pe Jesu wole okan re.
Bi o nfe wo agbala isimi,
Pe Jesu wole okan re
f Yemeji mi ti fo lo,
Mo b’Olorun mi laja,
Mo s’okan mi paya fun,
Jesu ti wole okan mi.
Amin.
877
S.M
Ma beru , nitori Emi wa pelu re, Gen.26:24

1. f F’eru re f’afefe;
N’ireti, ma foya;
p Olorun gbo mikanle re;
Y’o gbe ori re ga.

2. N’irumi at’ iji,


Y’o ona re fefe;
Duro de igba Re oru
Y’o pin s’ojo ayo,

3. p Okan re ha wuwo
O re emi re bi
f Gbon gbogbo ifoya kuro,
Le gbogbo eru lo.

4. mf B’o ko tile kuro ,


Sibe orun , aye
Nso p’Olorun wa lori te,
O njoba lododo

5. Fi yiyan on sise
Le ase re lowo;
Wo y’o si f’iyanu jewo
Ogbon at’ ipa Re.

6. Y’o han pe imo Re


Ggaju ero re lo
Gbat’ On ba yori ise na
Ti nfo o li aya ;

7 cr Iwo r’ailera wa
O si mo ero wa
di Gbe owo t;aye mu s;oke ,
Ti nfo li aya

8. N’nu iye tab’ iku,


K’a kede oto Re,
K’a so t’ ife on toju Re
Tit’ opin emi Wa.
Amin
878
D.C.M
Bi enikan ba wa ninu Kristi o di eda titun.Iikor.5:17

1. mf E wa tanna ooro kutu,


Mo odsan gangan ,
Pipon orun ni ojoro
di A nfe ti yara sa to.
A nfe enu bode orun,
Ita wura didan
A wa nfe orun ododo,
` Ti ki wo titi lae.

2. B’ireti giga wa l’aye


Si ntete saki to
Abawon melomelo ni
Nb’ agbada Kristian je;
A fe okan ti ki d’ese
Okan ti a we mo
Ohun lati yin Oba wa
L’osan ,l’oru titi

3. Nihin ‘gbagbo on reti mbe


Lati to wa soke
Lohun pipe alafia
Ju b’ti lefe lo
Niori iku Re
Ma je k’a subu l’ona Re
Nitori iku Re
K’;a so ade wu nu
Amin
879
6.6.8.6.8.8
E gba ajaga mi si orun nyin , enyin o si ni isimi fun okan nyin Mat.11:29

1. cr Mop simi le Jesui


Wo ni mo gbekele;
P Mo kun fun ese at’ osi
Li okan aya Re nikan
L’okasn are mi simi le.

2. mf Iwo Eni mimo


Baba simi n’nu Re
Eje etutu ti O ta
Lo si mbebe fun mi
cr Egun tan ,mod’alabukubun;
Mo simi ninu Baba mi.

3. mf Eru ese mi ni,


Wo l’oda mi n’ide;
cr Okan mi si fe lati gba
Ajara Re s’orun ;
f Ife Re t’o gba aya mi
So ise on lara d’ayo.

4. ff Ojo ologo na,


Isimi orun mbo
di Ese at’ irora y’o tan ,
Emi o si dele ile ileri
Okan mi o simi laelare0
Amin.
880
D.C.M
Iwo ni ibi iopamo OD 32:7

1. Jesu , Wo n’ibi ‘sadi mi,


Wo ni mo gbekele ;
Oro Re n’iranlowo mi,
cr Emi ailera ,
Nko ni ejo kan lati to,
Ko s’ohun ti un o wi;
f Eyi to pe Jesu mi ku,
Jesu mi ku fun mi.

2. mp Igba iji danwo ba nja,


T’ota ndoju ko mi
mf Ite anu n’isadi mi,
Nibe n’ireti mi’
Okan mi yio sa t’O wa
Gba banuje ba de;
f Ayo okan mi l’eyi pe,
Jesu mi ku fun mi.

3. mp Larin iyonu t’o wuwo


Teniyan ko le pa gba ;
Larin ibauje okan
Ati rora ara,
cr Ki lo le fun mi n’isimi
Ati suru b’eyi.
T’o ns’ eleri l’okan mi pe
f Jesu mi ku fun mi
Amin.
881
0.10.10.8 & Ref.
Awon eni irapada Oluwa nwon o ri ayo inu didun gba.Isa 35:10.

1. mf Bi iwo nfe idariji gba,


Alafia ti nle banuje lo;
Woke sodo Jesu t’o ku fun O,
Lati ra igbaala kikun .
cr Wa si abe agbelebu Re,
cr Wa isura aye yi sofo
di We nin eje t’o nsan lat’ oke
mf Gba igbala re ni kikun

2. mf Bi o nfe ki o joba l’okan re,


We ninu isun si gba iwosan ;
di Wa We ninu eje Odagutan
Gba igbala re ni kikun.

3. mf Bi o nfe ni igboya lati ja


Ma ninu n’nu mole at’ iwa mimo;
Lati ma sin ni omintra okan
Gba igbala re ni kikun.

4. mf Rom ‘agbelebu fun iwa Mimo


Ka oro aye yi s’ohun asan;
di Wole lese Re yuio we o mo,
Gbati igbala re ni kikun
Amin
882
8.7.8.7.D
Bi iwo ba gbagbo iwo o ri ogo Olorun.Jjn11.:40

1. B;o ti dun lati gbsa Jesu


di Gbo gegebi oro Re;
K’a simi lor’ ileri Re
mf Sa gbagbo l’Oluwa wi
f Mo gbekele n’gbagbogbo.
Jesu , Jesu \,Alabukun
Ki nle gbekele O si

2. mf B;o ti dun lati dun Jesu,


K;a gb’ eje wenumo Re
Igbagbo ni ki a fi bo
Sin eje wenumo na

3. mf B’o ti dun lati dun Jesu,


Ki nk ara ese sile ,
Ki ngb ayo iue isimi
Lati odo Jesu mi.

4. f Mo yo mo gbekele mi le O
Jesu mi, Alabukun ;
Mo mo pe O wa pelu mi
Ntoju mi titi dopin .
Amin
883
55.11.D.
Tire sa ni gbogbo ohun ti ise temi,Jn17:10

1. mf T’Olorun l’emi’ni Jesu


Ttunu nla l’eyi;
Mo layo nla pupo
N’nu Od-agutan
f Ire Oko Re si nmu okan mi Yo.

2. mf Iro ayo na
Niadun oto
Eni ba si ti ri paradise
Ati eje Re,
Iye ailopinni, orun ni laye

3. Mo sure tete
Lo s’ase t’orun;
T’ohun je ekun re t’ihinjeowo
Un o mo yi daju
Gba mba f’ayo lo
S’orun t’o ga julo,n’nu ife Jjesu.
Amin
884
8.6.8.6.8.8.8.3
Oluwa li apata mi, ilu olodi mi ati Olugbala mi.OD.18:2

1. mf Jesu j’ohun gbogbo fun mi,


Ayo at’ aye mi;
Onl’agbara min’gbakugba
Laisi Re , un o subu
N’gba banuje mo sa t;O lo
cr N’gba danwo , O mu nu mi dun
Ko s’eni to dabi Jesu;

2. mf iJesu , johun gbogbo fun mi,


Ore mi n’gba danwo,
Molo sodo Rre fun ‘bukun
Mo rigba ni kikun;
O ran orun ati ojo
At’ eso to pon fun kore,
At’ opolopo ibukun;
Ore mi.

3. mf Jesu j;ohun gogbo fun mi


Uno sa j’oloto s’
Un o se ore nlanla
T’o s’oloto si mi
Mo yege bi mo ba tele
O npa mi mo losan loru;
Em’o tele losan ‘ loru
Ore mi.

4. mf Jesu j;ohun gbogbo fun mi,


Un ko fe ore miran
Mo gbekele nisisiyi
Ati titi d’opin.
Igbesi aye alafia
Ti ko l’opin pel’ore yi
Ni y;o ipin mi titi;
f Ore mi
Amin
885
7.6.7.6 .&Ref
E ma rin nipa Emi enyin ki yio si mu ifekufe ti ara se.Gal.516

1. Gbati mo ti gba Jesu


Iyebiye lo je;
f Aye mi wa di Otun,
O si dabi Orun ,
Aye dabi Orun,
Aye dabi Orun
Aye dabi orun nihin
Gbati fe oruko
cr Jesu ba wonu okan lokan mi
Aye dabi Orun

2. Un o ko n’idalebi lokan
Sugbon ayo Orun
cr Mo f’ara mi f’Oluwa
Fun segun lor’ese

3. Mo nrin lona toro ni


T’ibnu je rira
Ife orun at’ ayo

4. mf Un ko gbe aye s’okan,


Iberu ko si mo;
Adun aye ko si le fa mi.
Mo ni orun nihin
Amin
886
7.7.6.D.&Ref
Kristi ti ra wa pada,Gal 3:13

1. f Ayo wa n’nu okan mi,


Eyi t’enu ko le so,
Gba Jesu njoba n’be
O le gbogbo ese lo
O m’ ojo rapada wa
Gba Jesu njoba n’be,
ff Gba Jesu njoba n’be
Alafia kun okan mi
At’ ayo ti ko lopin ,
Gba Jesu njoba n’be

2. f Ayo at’ alafia de


Ti y’o ma po titi lae
Gba Jesu njoba n’b
Ibukun nduro de mi
Ati segun t’ologo
Gba Jesu njoba n’be

3. f Ko je f’emi nikan le
Gba mo je nikan,
cr Gba Jesu njoba n’be;
O si nmu okan mi yo;
mf Mo fi gbogbo gbohun Re
Gba Jesu njoba n’be

4. cr Orun wa n’nu okan mi


B’igbi tile yi mi ka,
Ggba Jesu njoba n’be
Bi mo ti ntesiwaju
L’ona t’awon mimo nrin
Gba Jesu njoba n’be.
Amin.
887
8.7.78.7.D
Bi iwo ba le gbagbo , ohun gbogbo ni sise fun
eni ti o ba gbagbo Mk.9:23

1. mf Ohun gbogbo lo sise


F’eni t’o gba Jesu gbo
Oruko Re un ko Kegan mo
Otito Re ni mo di mu,
Cr Mo gbagbo pe ohun gbogbo
Ni sise fun mi ninu Kist’

2. cr O di aigbodo mase pe
Ki ese parun ninu mi,
Emi mo pe be ni. Yo ri
mf Mo gbekele l’ododo Jesu
B’iwo ba le s’ohun gbogbo
Emi na le se ninu Re.

3. mf B’aye ba kegan oro na.


Oro Olorun ko le ye.
Iwo nfo agbara ese
O daju pe iwo le se
Ko sohun to soro fun O;
Sise l’ohun gbogbo n’nu Re.

4. mf Sise l’ohun gbogbo fun O,


Fun krist’ agbara Olorun,
Fun mi gbati mo d’atunbi
Ti mo si di eda titun,
Ese ko le bori mi mo
Sise lohun gbogbo fun mi.

5. mf Sise l’ohun gbogbo fun O,


Fun Krist’ agbara ninu mi.
Tan ogo imole Re ka,
Ki nma wa fun ara mi mo
Ki nfihan isisiyi ,
Adun agbara ife Re.
Amin
888
8.7.8.
Emi ni Olusogutan rere.Jm 10:11

1. cr Ale ri olsogutan
To feran wa bi Jesu ,
Olugbala wa ti O nfe
] Ka ma pejo l’ese Re.

2. mf sEse ti eyin fi nfonka


B’abo-ran t’eru mba
mp Eyin ope , e se nsako
Kuro labe ife Re

3. mf Anu Olorun ti po to
O po bi omo okun;
Ododo Re kun fun ore
To po ju omiran lo

4. Ko si ibi ti a nkedun
F’ araye ju t’orun lo
Cr Nnibe li anf’oju anu
Wo gbogb’ asise eda

5. mf Idariji mbe f’ elese


Or’ofe mbe f’eni re
Anu mbe l’Od’Olugbala’
Iwosan mbe n’n eje Re.

6. f idande mbe lopolopo


N’nu eje ta sile;
Ayo mbe un gbogbo aye
N’nu iya Olori wa

7 N’tir’ ife Olorun boro


Ju oye eniyan lo
Je ife ‘Yanu pupo

8 Bi ife tiwa l’’ailetan


di A ba gbe okan wa le;
Aye wa iba wa le;
Ninu ife Oluwa .
Amin
889
L.M
Ese ti enyin kekere fi se ojo be enyin onigbabo kekreke.Mat 8:26

1. mp Sa dake okan mi
Oluwa re wa mbe
Eni ‘o ti se ileri
Yio fe mu u se

2. mf On ti fa o lowo
O mu o de ‘hinyi
Y;o pa mo la ewu ja
Ttit’ opin aye re

3. Nigbat’ iwo ti bo
Sinu wahala ri
Igbe re na ki on ha gbo
T’o si yo o kuro

4. B’ona ko tile dan


Yio mu o de ‘le
f Sa ti wahala aye tan
O san fun gbogbo Re
Amin
890
10.9.10.910.9.&Ref
Jesu so fun won pe emi wa pelu yin nigbogbo, titi o fi de opin aye, Mat28:20

1. mf Ore bi Jesu kosi laye yi


Oun nikan l’ore otito ;
Ore aye yi y’o fi wa sile ;
Sugbon Jesu ko je gbagbe wa
Ah ko je gbagbe wa;
Sugbon Jesu ko je ko je gbagbe

2. Akoko nkoja lo laifotape;


A f’oko kan sunmole wa si
Onidajo mbo, gongo, yio so;
Awa wi kan kosi l’ ojo na

3. Duro d’Oluwa, ma si yemeji


Ohunkohun t’o wu ko le de
Gbat’o ro pin ‘ranwo Re y’o de
Eni yanu l’oba Ooluwa
Amin
891
C.M
Bikosepe a tun eniyan bi on kol ri ijoba Olorun.Jn.3:3

1. f Okan mi bale, mo soji


N’gbati mo mo Jesu ;
Gbogbo ese mi l’O fi ji;
Ogo f’ Atobiju

2. mf L’ojo kan ‘o d’orun


Wahala y;o dopin
Ibanuje ko ni si mo;
Ayo y;o tiwa

3. f Gbogbo aye ba je temi


Asan ni eyi je
Oro ti kole ddibaje
L’o mbe fun mi loke
Amin
892
8.7.8.7.8.7.
Ki oju Re le si si ile li osan ati li oru I A Oba8:29

1. mf Kristi ipile t’o daju


Krist’ l’ori Igunle
Asan yan at’ iyebiye
O so gbogbo Ijo lu
Igbekele Re titit

2. mp Si tempili yi l’la npe O


Jo, wa loni, Oluwa;
Gbo ebe eniyan Re
Ma da ekun ibukun Re
Sinu ile yi titi

3. Fun awon omo Re l’ebun


Ti won ba toro nihin
Ore ti won ba si ri gba
Ko ma je ti won titi
Nikeyin , ninu ogo Re
Ki won ma ba O joba

4. ff Ogo at’ola fun Baba,


Ogo at ola fun f’Omo,
Ogo at’ fun Emi,
Mtalokan titi lae
At’ ayeraye, okanna.
Amin
893
6.6.6.6.8.8
Ibukun ni fun awon ti ngbe inu ile Rre OD.84:4

1. mf Kristi n’ipile wa,


Lori Re lao kole
Awon mimo nikan
L’o ngb’ agbala Orun
Ireti wa
T’ore aye
T’ayo ti mbo
Wa n’nu fe Re

2. f Agbala mimo yi
Yo ho f’orin iyin;
Ao korin s l
Metalokan mimo,
Be lao f’orin
Ayo kede
Oruko Re
Titi aye

3. mf Olorun Olore,
F’iyesimi nihin;
Gbaeje t;a mu wa
At’ebe wa gbogbo
K’o si f’opo
‘bukun dahun
Adura wa
Nigbagbogbo.

4. cr Nihin je k’ore RE
t’ Ntoro lat’ Orun
Bo ‘s ori si wa Lekan
Ko ma si tun lo mo
di Tit’ ojo na
T’ao s’akojo
P Awon mimo
Sib’isimi
Amin
894
L.M
Ki oju Re le sisi ile yi osan ati li oruI A Oba 8:29

1. mf A fi ipile lele
Ni oruko Re Oluwa
Awa nbe o, Oluwa
Ma toju ibi mimo

2. Gba eniyan Re ba nwa O,


T’elese nwa O, n’ile yi,
Gbo, Olorun lat’ orun wa
F’ese won ji won, Olorun

3. Gbat’ awon ranse Re nihin


Ba nwasu hinere Kristi;
Sibe se nipa oruko Re

4. f Gb’ awon omode ba si ni nko


Hosanna si Kristi Ob won
K’orun at’ aye jo gberin.

5. f Jjeofa O ha ba ni gbe
Ni aye burubu wa yi
Jesu O ha je Oba wa
K’Emi mimo si ma gbe hin

6. f Ma je ki ogo Re kuro
Ninu ile ti a nko yi
Se joba Re ni okan wa.
Si te ite Re sinu wa.
Amin
895
S.M
Emi o si fi ogo kun ile yi, Oluwa awon omo ogun wi.Hag.2:7

1. f Olorun wa tobi,
E Je iyin Re po
O f’ile sin Re se bugbe
At’ ibujoko Re

2. f Temipli or’ofe,
A won ti dara to
Awon li ola ilu wa
At’odi ile wa

3. cr Ni Sion , Olorun
L’abo n’igba ponju
ff Igabala Rre ti logo to
Nn’nu awon afin Re

4. mp Bi iponju ba de
cr A o lo si le Re
di A o ranti ore ofe Re,
Ao wa ‘gbala nibe
Amin
896
7.5.7.5.7.5.8.8.
Ki o si gbo li orun ibugbe Re , gbo . ki O si dariji, I A Oba 8:30

1. mp Gb’alare ti nwa ‘simi ‘


Sa wa odo Re
Gba eni ti orun now
Gb eru re le O,
Gba eni nwa alafia
Ke pe oko Re
Gb’elese ti nwa iye
Wole l’ese Re
cr Jo , Oluwa , gbo igbe won
f Lati ibugbe Rre l’Orun.

2. mp Gba eni ti aye su


Gb’okan re s’oke
Gbat asko ba pada
S’ife Baba re
T’agberaga ba wole
Lati w’oju Re
Tt’eni ebi kese re
cr Jo, Oluwa , gbo igbe won
f Lati ibugbe Re l’Orun.

3. mp Gbati alejo nwa ‘bugbe


Ti y;o simi si
Ti elebi nwa onje
T’otosi nw ore
Gbat’atuko loju’ bu
Gb’okan re si O.
cr Jo okan gbo li igbe won
f Lati ibugbe Re l’Orun.

4. mp Gbati eni tinsise


Li arin ilu
T’ols’agutan n;igbe
P’oko Olorun;
Gbati awon alagbara,
T’adun aye su.
Ti nlepa ayo t’orun
Pe oko nla ni;
cr Jo, Oluwa , gbo igbe won
f Lati Ibugbe Re l’Orun
5. mp Gbati ewe at’ odo won
Ati arugbo
Ba nsaferi oju Re
Nnipa adura ;
Gbatopo ba nke pe O,
Nigbati alaini re
Ko osi re wa
cr Jo, Oluwa gbo igbe won
Lati ibugbe Re l’orun

6. mp Gba gbogb’ eda nkerora


N’nu iponju won
Ti omo asako
Mi imi edun
T’ijo Re t’on t’omije
Ba nwa ibugbe,
Ti nfi edun ke wipe
Jesu, jare wa
cr Jo, Oluwa , gbo igbe won.
f Lati ibugbe Re lorun.
Amin
897
7.6 7.6 7.67.6.
Nitori ogo Oluwa kun ile Oluwa I Aoba 8:11

1. mf ‘Wo Enu ti owo Re


Mu wa d’ojo oni
cr Jo tewo gba ope wa,
F’ eti s’adura wa
Ki imurasile wa
Fun isin oni je
Lati ‘ ara wa fun O,
Pel’okan isokan.

2. f A yin O fun ile yi


T;a ko li ase Re ;
F’a won t’o se iranwo
Ffun ise kiko re;
Je ki a ri ogo Re;
Ninu Tempili Re
di Nitor’ asan l’ewa re
Bi O ko si nibe.

3. mf Nigbati a ba npejo
Lti josin nihin,
cr Je k’a r’agbara oto
Kadura wa goke;
K’osise gb’ okan s’oke
Si ohun li orun,
Ki’ t’agba t’ewe l’okun
Ki aye mo fe Re

4. mf B’odun ti nyi lu odun


Tti ife toto npo
Si ile mimo Rre yi
Ti a si nranti re
cr Ki ola at’ ogo Re
Je eyi titi lae
Pe opolopo t’ihin
Ri, ona s’odo Re.,

5. f Ranwo awon Baba wa ,


Ayo on reti wa ;
Oluwa on reti wa
Oluwa fun wa l’ebun
Opo ojo l’aye
‘Wo mo edun okan wa
A mbe niwaju Re
Jo, wa f’oju rereRe
Se ;le yi ni Ttire
Amin
898
L.M
Oluwa Olorun tetisile si adura ti iranse re ngba loni I A Oba 8:28

1. mf Pelu wa, Oluwa loni


B’a ti nya ‘le yio si Mimo,
Gbo adura iranse Re
K’o si f’eti igbe won

2. Jek a ri alafia nihin,


At’ ife ati otito;
Da won t;a ni lara sile
K’okan won kun f’ ore ofe

3. mp Gbo mi edun awon tire


Ki alare ri isimi;
Gbo gbe onirobinuje
Si bukumn fun okan gbogbo,

4. Fi itara kun okan wa,


Si je ki okan wa gbona
Gbat’a ngbo hinere hinin
T’a si nkede oruko Re.

5. mf So oku d’alaye nihin ,


K’’o di korin , k’aditi gbo
Si fun awon onirele
N’ifji at’ alafia.

6. f Se ile yi n’alaye nihin,


K’a mari oju Re nihin
K’eyi le ile Olorun
Ati enu bode orun.
Amin
899
L.M
Nigbati a fi ipile ile yi lele , awon pupo si ho iho nla fun nla fun ayo.Esra 3:12

1. f Olorun , a yin ‘toju Rre


Lori agbala mimo yi
Ota ko gbodo gbogun ti,
K’o daya fo olusin Re

2. f Ao mo giri yi f’ ola Re
K’o ma ho fun ‘yin Re titi
Gbat’o ba si sokale wa
F’ore-ofe Re kunnu re

3. mf sGbat ojo nla ni ba si lejo,


T’Olorun y’oi d’aye lejo
cr K’o han fun gbogbo aye pe
f Opo l’a bi ogo nihin .
Amin
900
6.5.6.5.D
Nioriti a fi ipile re sole lori apata Mat 7:25

1. mf Kristi ni ipile
Ile t;a nko yi;
K’odi re je ‘gbala
Ki ona re je yin
Ki iloro sowon
L’oju Oluwa
K’okan awon ‘
Nihin je Mimo

2. mf Nihin ni k’Emi Re
Ma gbo eje wa;
K’a m’alaisan r’ iwosan,
K’oniirbinuje;
Rri dariji gba;
K’awon t;o ti pinya
Tun ni irepo.

3. mf Jeki ri eri
Pe , o mbe nihin ;
K’awon t;a de l’ewon
D’ominira nihin;
cr K’imole tan nihin ;
Si awon Ttire;
Lati gbe wa soke
Si ohun t’orun

4. f Nihin ni k’a juba


Olorun Baba
Ati Kristi Omo
Pel’Emi Mimo
Titi gbogbo eda
Y;o wole fun O
Ti won o ma yin I,
Oluwa aye.
Amin
901
12.912.9&.Ref
Solomoni sibere si iko ile –Oluwa.II kro.3:1

1. mf O yigigi, Oba Onise ‘yanu


Atobiju Oludunmare,
Abani-kedun . Oluanlowo alain
Iwo lope, ye Olugbala
f Dide , Olorun Solomoni , didem,
Ba wa ko ile yi pari,
Je k’a npin lati josin nibe
Pelu orin ‘yin on ope

2. cr Iwo Olorun to bukun fun Jakobu,


Ran wa lowo lori ise yi
Ki ‘lehin orun si, k;ojo bukun si ro
S’ori t’gba t’ewe Ijo wa.

3. f Eje ka fi yin at’ ope f’ Oluwa


Fun ore ofe nla to sun fun wa
Lati ko ko ile mimo nigba aye wa
Fun ogo oruko Oluwa.

4. cr E ranti ilreri t’ Olugbala wa se


Lat’ enu awon iranse Re
Pe , ati fi isura nla pamo fun wa
Nibi kokoro ko le ba je.

5. Iwo Olorun eleda ohun gbogbo


Jeka ni ipin n’nu ise yi
mf Fun wa n’irepo ati isokan emi.
Lati pari le yi f’ogo Re

6. mf Bi Baba ti f’ owo’tun Re gbe Jesu ga


Leyin t’ise igbala pari;
cr Fun wa ni segun , ko si gbe ijo yi ga,
K;O si di ile
Amin
902
8.7.8.74.7
Nitori ile adura li a o ma pe ile mi fun gbogbo eniyan .Isa 56:7

1 f Olorun Baba , Ologo ,


T’ O joko lor’ ite lae
Awa omo Re teriba ,
A nw’ojure Re nikan ;
ff Olouwa wa,
p Jeki anu Re han nikan

2 f Olorun Omo ‘lugbala ,


T’O duro n’ite anu.
O ti jeje ojure Re
Nibit eeyan Re ba pe;
ff Alabukun
P Bukun wa b’a ti dur

3 f Olorun Emi , to new ni,


Mole, lye , Agbara ,
Owo ina mimo loke,
Mu k’oju Re dan si wa
ff Emi Mimo
Se ago yi ni Tire .

4 f Baba ,Omo , ati Emi,


Ife sokan , sokale;
Ki ore-ofe Re si wa
So ile yi di Tire;
ff Jehofa nla,
Ran ogo dahun si wa.
Amin
903
L.M
Adura ki adura tabi ebe ki ebe ti a ba ti odo enikan gba ki Iwo ki o gbo ki o si dahun
llkro.6:29-30

1 mf Nihin, l’oko Re Oluwa ,


A ko le rupe yi fun O,
Yan fun ‘bugbe Re pataki,
K’O si so lowo nsise.

2 mp Gb’eyan Re ba nwa O nihin,


T’else mbebe fun iye,
Gbo lat’ ibugbe Re Orun,
Gbat’ O ba gbo , k’O dariji.

3 mf Gbat’ojise Re ba nwasu
Ihinrere Jesu nihin,
Nip’agbara oko gberin nla
‘ K’a ri ami on se yanu.

4 Gbt’ ohun ewe ba nkorin


Hosana s’Oba won l’oke
Ki aye at’ orun gberin na.
Ki angeli ko Hosana.

5 f K’ogo Re ma f’hin le lae.


Sibe , ma yan le yi nikan ,
K’ijoba Re d’okan gbogbo
T’ite Re si gbogbo aye.
Amin
904
L.M
Nitori nibiti eni meji tabi meta ba ko ara won jo li oruko mi, nibe li emi o wa li arin
won.Mat.18:20

1 mf Olorun Baba , Krist’ Omo,


Ati Emi , Metalokan,
Gba ore ti a mu wa yi,
T’a fi ife onigbagbo se’

2 K’imole oro Re f’ Oye


F’ agba ati ewe nihin,
Gbrin ore ni s’okan pupo
Ti gba la lowo ese.

3 Nnihin , Ki Jesu f’ ipa han,


Ti so okun di imole,
K’O si ilekun fe paya,
T’o yo si ibukun loke,

4 f Jesu Oluwa , Alade,


Wo t’ awon mimo nwole fun,
Gba ore iyin t’a fun O,
K’O si f’ogo Re kun le yi.
Amin
905
7.7.7.7D
Ibukun ni fun awon ti ngbe inu ile re;OD 84:4

1 f Alafia fun le yi
At’ awon ti ngbe nu re;
K’alafia Olorun
B’eni alafia gbe,
Jeki Emi sokale;
K’ibukun na ba le wa
Om’ alafia gb’ade re
Ekun rere or’ofe.

2 mf Kristi, Wo l’Oluwa mi,


Je ki nje akede Re ;
Mase airanti oro Re ;
Be won wo si be mi wo’
K’igba la wo ile yi
F’ awon ti ngbe inu re
Gba okan wa lowo ‘ese.
Fi wa se ibugbe Re.

3 mf Mase jek’ a se are


Titi ileri na y’o se ,
Titi ao fi je Tire
Nipa isodimimo;
cr Fun wa n’ife t’o akotun,
K’a je ri re sonu ,
K’a je tempili Olorun ,
Baba , Omo at, Emi.
Amin.
906
11.10.11.10.11.10
E lo wasu ihinrere fun gbogbo eda .Mk.16:15

1 mf Yo awon ti nsegbe ,sajo eni nku,


cr F’anu ja won kuro ninu ese’
Kef’awon ti nsina gb’ eni subu ro,
So fun won pe , Jesu le gba won la
p Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
cr Alanu ni Jesu ,yio gbala.

2 mf`Bi won tile gan. Sibe O aduro


Lati gb’ omo t’o ronupiwada
p Sa f’itara ro won , si ro ewon jeje,
O n o dariji bi won je gbagbo.

3 mf Ero okan eda ti esu te pa


Ni ore-ofe le tun mu pada ;
Okan ti o gb’ ogbe t;a fowo ife;
At’ inu rere soji y’’o korin

4 Yo Oluwa ti nsegbe ise tire ni,


Oluwa yio fagbara fun O,
Fi suru ro won pada s’ona toro,
So f’asako p’Olugbala ti ku.
Amin
907
10.10.10.10
E wa eniyan tikara nyin si apakan , ki enyin ki o si simi die,Mat6:31

1 mp E wa sapakan , k’e simi die


Mo mo are ati wahala yin.
E nu ogun oju yin nu kuro,
cr K’e ti gb’ agbara n’nu gbara Mi.

2 mf E takefe s’ohun adun aye.


E wa fun idapo t’aye ko mo
Enikan wa l’odo Mi on Baba ,
L’odo Mi on Baba, egbe yin kun.

3 E wa so gbogb’ohun e se fun mi’


So t’isegun ati t’isubu yin ;
p Mo mo b’ise emi ti soro to,
cr Ade t’o dara t’on t’omije ni,

4 mp E wa simi ajo na pupo,


Are o mu yin, e o ku lona ;
cr Onije iye wa nihin e wa je
Nihin l’omi iye wa, e wa mu.
Amin
908
L.M
E si kiyesi, Emi wa pelu yin nigbagbogbo titi o fi de opin aye.Mat.28:20

1 Gbati Jesu g’oke r’orun


N’isegun lori ota Re;
O tu ebun sori aye,
Ore Re si tan kakiri.

2 cr Nibe l’Aposteli ti dide,


Mimo won tayo okiki
Bi won l’awon eni rele
Ti alufa at’ oluko.

3 f Kristi l’orisun ebun won


On ni iye or’ofe won
B’o ti nf’owo Re gbe won ro
Won duro sinsin n’nu ponju.

4 cr Be n’iran won ki o dase


Titi aye yo fi dopin ;
Nipa won ni ljo tikun
Yo dide, y’o si ma gbile.

5 f Jesu, je ki okan wa mo
Orisun ibukun wonyi;
K’alufa at’ ljo yin O,
Titi aye ainpekun.
Amin
909
7.6.7.6.D
E ma duro sisin laiyeye, ki e si ma po si ni ise Oluwa nigbagbogbo.llkro.15:58

1 mf Oluwa kore emi


Ninu oko aye,
Nibi t’ awon angeli
Y’o ko ki won jo,
cr Gb’awon wonyi fun se Re
Fi ife s’okan won.
Je k’a ti owo won mu
Joba Re Yara de.

2 cr Fi won se alagbase
L’ogbon Re , Oluwa
Fun won ni li Olorun
Lati sise fun O,
Gbat’ O ba pe won rele
di Je k’ote won lorun
Pe , awon pin n’nu lala
Ti nmu joba Rre bo.

3 mf Ma wa pelu won , Baba


Ma so won , Emi Mimo
Metalokan laelae
di Fi won joye alufa
Lati f’oto sin O,
Si fi ore re kun won
Loni ati laelae.

4 mf Wa , iwo Emi Mimo


Fi imole kun wa
Fi ewu atilbawon
Wo wa ka fun laulau,
N’nu ile mimo Re
Yas eeyan Re si mimo
Ni gbogbo ile yi.
Amin
910
C.M
Ki enyin fi ara nyin rubo si Olorun eyi ni ise isin nyin ti o tona Rom.12:1

1 mf O nise Olorun , dide’


Mo riri Olorun,
cr B’o ti wu k’ogun gbona to
Wo o ja b’akoni.

2 Ilopo ibukun ni fun


Okan eni t’o O so
Pe Olorun mbe l’oju ja
Gbat’ oju wa ko ri.

3 mf Olorun ju b’a
Giga si l’ona
Eni n’ife ewe l’okan
L’o le ri ona na,

4 cr Mase ka iyin eda si.


Padanu f’Olorun ;
di Jesui jer’aye nipa egan.
O npe o s’ona Re

5 mf Oto ni y’o leke danadan


Niwon t’ Olorun mbe
Isote ni iyemeji;
Ese n’ifasehin.
Amin.
911
C.M
Ibukun Ew si mbe lara awoneniyan e.OD.3:8

1 mf Iwo t’o nmu okan mole


Nipa mole at’ orun wa;
di T’o si nse iri ibukun
Sor’ awon ti nsa feri Re

2 mf Jo masai fi ibukun Re
Fun oluko at’ akeko;
Ki ijo Re le je mimo,
K’atupa Re ma jo gere.

3 F’okan mimo fun oluko


Igbagbo reti at’ ife
Ki won je nit’ Iwo ti ko,
Ki won le j’oluko rere

4 f’eti igboran f’akeko


Okan rele at’ ailetan ;
Talaka t’o kun f’ebun yi
San ju oba aye yi lo.

5 cr Bukun oluso at’ agutan ,


Ki won j’okan labe so Re
Ki won ma f’okan kan sona.
Tit’aye osi yi y’opin.

6 Baba b’awa n’nu ore Re


L’aye yi l’a o ti logo;
K’a to koja s’oke orun
Lao mo ohun ti aiku je.
Amin
912
L.M
Won tele ko fi awon tikarawon fun Oluwa .IIKro 8:5

1 K’emi n’tori eru eniyan


Da se eni duro n’nu mi?
Tabi ki njeri f’Oluwa
L’oro on ise laifoya

2 Ifojuro eniyan le
Mmu mi pa or’ Olorun mo/
di Bawo l’emi y’o ti se le
Duro loju ibinu Re

3 cr K’emi ha din oro Re ku,


K’o le ba ti aye lara;
Tabi , ki nsa f’agbelebu ,
Ki nle jere ohun aye?

4 mp Olugbala , oju Re ri.


Gbogbo ero nu okan mi.
p Ohun kan ha gba mi laya
Faji aye tab iyin re?

5 mf Ife kristi ni o nro mi


Lati wa emi t’o sako;
mp Ki nfi ebe ati ekun
Ja won l’enu isa oku

6 mp Mo ni emi atara , mi wa.


Bi won le wulo f’oto Re’
cr Mu imo Re se Oluwa;
K’a se fe Re k’a juba Re

7 mf Fun mi l’agbara , Olorun ;


Iji ba ara ba san,
Eleri ooto ni un o je
Mo le s’ohun gbogbo n’nu Re
Amin
913
S.M
Sugbon nitori oro re omi o ju awon na si isale.
I kro 5:5

1 Jesu , b ‘a nfunrugbin
Oro ‘ye lase Rre;
B’a ti owo Re b’omiran,
Rugbin na y’o dagba.

2 mf Ipa or’ ofe Rre


Y’o mu bisi pupo
Y’o so oloto di pupo
Ti nwa fun ogo Re.

3 mf Ro ojo ibukun- rere Re


Tti ihin –rere Rre
K’agbara ti ny’okan pada.
Bba iranse Re gbe.

4 cr Fun opo eniyan


N’ife isodotun;
F’ayo or’ofe pese won.
F’ayo kikun loke.
Amin
914
S.M
E di amura nyin ki fitila nyin si ma tan Lk.12:35

1 mf Iranse Oluwa;
E duro nid’ise
E toju oro mimo
E ma sona Rre sa.

2 Je k’imole yin tan.


E tunfitila se.
E damure girigiri ,
Oruko Re l’eru.

3 Sora l’ase Jesu.


B’a ti nsoko jina
p B’ o ba kuku ti kan lekun.
mp Ki e si fun logan.

4 f Iranse re l’eni
Tti a ba nipo yi;
Ayo l’on o fi r’ Oluwa,
Yo f’ola de l’ade

5 mf Kristi tikalare ,
Y’o te tabili fun;
Yo gb’ ori iranse na se.
Larin egbe angeli.
Amin
915
L.M
Ki emi ki o le mo bi a ti soro li akoko fun alare/Isa 50:4

1 mf Ko mi Oluwa, bi a ti
Je gbohungbohun oro Re.
B’o ti wa mi, je k’emi wa.
Awon omo Re ti nu.

2 To mi, Oluwa ki nle to.


Awon asako si ona ;
Bo mi Oluwa, ki nle fi.
Manna Re b’awon t’ebi npa

3 f Fun mi l’agbara; fi ese


Mi mule lori apata
di Ki nle na owo igbala
S’awon t’o nri sinu ese.

4 mf Ko mi Oluwa , kinle fi.


Eko rere Re k’elomi;
F’iye f’oro mi, k’o le fo
De ikoko gbogbo okan.

5 f Fi isimi didun Re fun mi,


Ki nle mo, bo ti ye lati
Fi pelepele s’oro Re
Fun awon ti are ti mu.

6 f Fi ekun ore Re fun mi.


Titi okan mi y’o fi kun
Fun tara l’ero at’ oro
Lati kede fe oun yin Re.

7 Lo mi, Oluwa a n’emi


Bi o ti fe, nigbakugba,
ff Titi em’o fi r’oju Re.
Ti un o opin ninu ogo Re.
Amin
916
S.M
Alabukun fun ni enyin ti nfunrugbin niha omi gbogbo. Isa 32:20

1 f Fun ‘rugbin l’owuro,


Ma simi tit’ale;
F’eru on ‘yemeji sile.
Ma fun s’ibi gbogbo.

2 mf Wo ko mo ‘yi ti nhu,
T’ore tabi t’ale.
Ore-ofe yoo pamo.
Bbi t’o wu ko bo si.

3 Yoo si hu jade
L’ewu tutu yoyo;
Beni t’o si dagba s’oke,
Y’o s’ eso nikeyin.

4 Wo k’o y’o sise lasan


Ojo, iri, Orun
Yoo jumo es ise po.
Fun ikore orun.

5 f Nje nikehin ojo.


Nigbat’ opin ba de,
Awon angeli y’o si wa ko
Ikore lo sile.
Amin
917
C.M
Niti ise sise, E mase sole.Rom.12:11

1 mf A tun pe mi s’idi se mi
Un o fayo sa pa mi;
Un o fi okan kan se ‘se mi;
Oluwa , l’oko Re.

2 Iwo l’opin gbogbo


‘Wo nikan ni mo ri;
cr Ohun ti se Tire ;
Jesu da ebun t’emi yi;
Mo ebo nla Tire.

4 B’a ba so ‘se mi di yiye,


On yio tewogba
Inu Re y’o si dun si mi,
Ti mo je omo Re.
Amin
918
8.7.8.7.8.7.
Emi wa pelu yin ani titi de opin aye.Mat.28:20

1 mf Sin awon onse Re sin won.


W’oba efufu igbi;
A de won , O da won sile,
Won nlo ‘da eru ni de;
cr Wa pelu won , wa pelu won.
Apa Re, l’o le gbala .

2 Won f’ile at’ ore sile


Ni ase Re , Oluwa ;
N’ile ati loju omi
Je Alafehinti won,
cr Jo pelu won , jo pelu won.
Si ma to won laitlewu.

3 mp Biti’se won ko m’eso wa.


T’o dabi ‘se won jasan;
Sunmo won l’anu Re , Jesu
Mu ireti won duro
Ran won lowo ,ran won lowo
K’itara won tun soji.

4 mf N’nu opolopo isoro,


K’won gbekele O, Jesu
Gbat’ ise na ba si ngbile,
Ki won mase gberaga;
cr Ma fi won ‘le ma fi won ‘le.
Titi won or’oju Rre.

5 f Nibiti won o’f’ayo ka


Eso irugbin aye;
Nnibiti won o wa titi
Lodo Olupamo won,
Pelu’ segun , pelu segun
Won o maa korin Jesu.
Amin
919
6.6.4.6.6.6.4
Oluwa si mba won sise Mk.16:20.

1 f Oluwa wa mimo,
Ti ogun orun nyin.
Masai gbo wa.;
Kerubu , Serafu,
At’ awon angeli.
S’odo Re ni won nmu
Iyin won wa.

2 mp Fun oro Re n’ipa,


Bukun ‘ranse Re yi,
Gba ise re;
Bi Jesu si ti nfi
Ami si oro re.
Ran Emi Re mimo
Lati fi han.

3 mf B’odun ti nrekoja,
Ki ayo ma posi
Ju t’o oni lo,
Yan kun ‘nu ile na,
Ran ‘ranse Re lowo ,
K’aye gba oto Re.
Oluwa wa.
Amin
920
C.M
Ohun na wipe, kigbe, Isa 40:6

1 mf Jek’alore Sion dide


Gba ipe fun ‘ra won;
Jeki won gba ase wuwo
Lat’enu Oluwa.

2 Ki ‘se ise kekere ni


A nfe oluso si;
O to kun angeli l’okan,
O kun Jesu lowo.

3 Won nso okan ti Oluwa


F’ogo orun ‘le fun
Okan ti yio wa titi lae
N’nu ayo tab’ egbe.

4 mp K’awon pa le ri Jesu na
Bi Olugbala won.
Sis’okan won l’ojojumo
Ki won le so fun O,
Amin
921
L.M
Ki enyin ki o be Oluwa lkore, ki o le ran alagbase sinu ikore Re, Lk. 10:2.

1 mp Olorun ‘kore , te ti Rre


F’ara Re han l’ogun Sion;
Rran ojise t’o n’itara,
T’o yara lati gb’ase Re.

2 mp Wo wa l’oju Oluwa wa,


Ikore pon , o nre dede;
Ile nla si siwaju wa.
Ise po, osise kere.

3 mp Fi owo agbara Re to,


Omo Sion nibi gbogbo
Bi alore ‘gbala ofe,
Ki won bukun iran kiku.
Amin
922
L.M
E gba awon ti nse olori yin gbo, ki e si fi ori yin bale, nitori won nso eso nitori okan yin.
Heb.13:17

1 mf O wo l’eni orooro Re,


L’ojise oro mimo Re.
Ipo eni owo l’o wa.
Jek’a f’iyin at’ ola fun.

2 Ipo elegbe n’ipo re


Aso ti ko fe abawon,
Jek’a fi ife ran lowo ,
K’a fi irele gb’oro re

3 Niwon b’o ti wu O lati


Fi se oluso emi wa,
p Fun ni suru lati to wa,
Ati opo if’ara da,

4 mp Ma jek’ise wa mu binu,
Ki iwa wa tan ni suru;
Fun l’agbara bi ojo re.
B’ ipo re, fun l’or-ofe Re,

5 mp Jek’ar’ewa Re l’ara re,


K’o ma ra ran n’nu iwa pele,
K’o mo ‘po re bi oliso,
K’a mo ti b’agutan re.
Amin
923
S.M
E ma ko won lati ma kiyesi kristi,
Ohun gbogbo Mat.28:20

1 Eyin ‘ranse Kristi,


Gbo ohun ipe Re ;
E tele ona t’O fi han,
Eyi t’a pe yin si.

2 mf Baba ti eyin nsin,


Alagbara ni se;
E gbekele ileri Re
f E ja bi okunrin .

3 Lo f’Olugbala han
p Ati anu otosi elese,
Ninu omo Adam’

4 f L’oruko Jesu wa,


cr A ki yin , ona re’
A mbe Eni t’o ran yin lo.
K’O busi ise yin.
Amin
924
11.11.11.11.&.Ref.
Niroripe Oluwa Olorun re on ni O mba lo .Deut 31:6

1 mf Jesu y’o pelu rel’ona re gbogbo,


Jesu y’o pelu re, y’o si maa to o
Larin asale ati l’ori oke
Jesu y’o wa pelu re nigba gbogbo.
f Jesu y’o pelu re, Jesu y’o pelu re.
Y’o je ore at’ olutunu fun O,
Jesu y’o pelu re, Jesu y’o pelu re.
Jesu y’o pelu re, y’o pelu re.

2 Jjesu y’o perlu re, l’ona re gbogbo


Jesu y’o pelu re, y’o si di mu
mp Larin afonifoji ibanuje,
Jesu y’o pelu re, ma so reti nu.

3 Jesu y’o pelu re, l’ona gbogbo,


Jesu y’o pelu re, l’ona ajo re,
cr Larin isan danwo s’ona ilu ni.
Jesu y’o pelu re, sa gbeke re l’E.
Amin
925
L.M
Olorun igbala wa, Eni ti igbekele eniyan gbogbo opin ile aye ati okun ti o jina rere
.OD65:5

1 Baba , jowo gb’adura wa,


Bi a ti nlo l’oju omi;
Iwo maa je ebute wa,
At’ ile wa l’oju omi.

2 p Jesu Olugbala , Wo ti
O ti mu ji dake roro,
cr Maa je ayo fun asofo,
F’isimi f’okan aibale,

3 mf Wo Emi Mimo Eni ti,


O ra baba l’oju omi,
Pase ‘bukun l’akoko yi,
Ffi ipa Re mu wa soji.

4 f ‘Wo Olorun Metalokan,


Ti awa nsin , ti awa mbo
Maa se abo wa laye yi
Ati ayo li orun.
Amin
926
8.8.8.D
Awon ti o nsise ninu omi nla won ri ise Oluwa , ati ise iyanu Re ninu ibu.OD.107:23-24

1 mf Baba wa Olodunmare,
‘Wo t’o kawo igbi omi,
‘Wo t’o ti f’ipo okun fun,
Ti ko le re ibe koja;
p crGbo tiwa, gbat’ a nkepe O.
di F’awon t’o wa l’oju omi.

2 mf Olugbala ‘Wo t’oro Re.


Mu igbi omi pa roro,
T’O sun enipe ko si nkan
p crGbo ti wa, gbat’ a nkepe O
di F’awon t’o wa l’oju omi.

3 mf Wo Emi Mimo , t’o rado


B’omi aye ni jo kini ;
Tt’o mu binu re pa roro
Oluwa mole at’ iye
P crGbo tiwa, gbat’ a nkepe O,
di F’awon t’o wa l’oju omi.

4 f Metalokan, alagbara ;
Dabobo won ninu ewu,
L’owo ina atoi iji.
L’owo ina at’ ota;
ff Si je k’a maa korin ‘yin Re.
di L’or’ ile ati lor’ omi.
Amnin
927
9.8.9.9.8&. Ref.
Oluwa On ni o nlo saju re,On ni yio pelu re.Deut, 31:8

cr K’Olorun so o k’a tun pade


Ki imoran Re gbe o ro;
K’o ka o mo so o agutan Re.
mf K’a pade -------k’a tun pade
K’a pade -------- l’ese Jesu;
K’a pade ------- k’apade
K’Olorun so o k’apade

2 cr K’Olorun so o k’a tun pade


K’of’iye Re dabobo o,
K’o maa pese fun aini re,
K’Olorun so o k’a tun pade.

3 mp K’Olorun so o k’a tun pade


cr K’of’owo ‘fe Rre gba o mu,
K’Olorun so o k’a tun pade

4 mf K’Olorun so o k’a tun pade


K’o fi ife rado bo o,
K’o opa oro iku fun O,
K’Olorun so o ,ka tun pade
Amin
928
L.M
Abomi mbe lodo Olorun.OD.7:10.

1 mf Pelu mi nibiti mo nlo,


Ko mi l’ohun t’emi o se
Pase ero at’ oro mi
K’o f’ese mi ona Re.

2 Fi opo ife Re fun mi


Maa se alabo mi laelae
Fi edidi Re s’aye mi,
Jeki Emi Rre pelu mi,

3 Ko mi bi a ti gbadura
Si jeki emi gba O gbo;
Ki nkori nkan t’O ko fe
Ki n si fe ohun ohun ti o fe .
Amin
929
S.M
Ohun rere ni lati ma fi ope fun Oluwa.

1 cr A mbe l’aye sibe


A si tun ‘ra ri’
f Ogo at’ iyin fun Jjesu
A mbe niwaju Re.

3 mp Iponju t’a ti ri,


Iya ti a ti je
Ija l’ode, eru n’inu,
Leyin t’a pe kehin.

4 mf Sugbon Jesu fi fe.


Y’o wa n’nu gbogbo re.
O si nran wa lowo sibe.
O npa emi wa mo,

5 f E je ki a maa fi.
Rrpada Re s’ogo
Tti y’o gba wa la se opin.
Gbat’ a ki o se mo,

6 di K’a gbe agbelebu ,


Titi la o gb’ ade
K’a ko ohun gbogbo s’ofo
K’a le jere Jesu.
Amin
930
S.M
Ohun o si fun yin li Olutunnu miran, ki o le ma ba yin gbe.Jn.14:16

1 di Jesu Wo li a now
A d’ileri Re mu
Pe, Wo y’o wa larin awa.
Tt’o pejo l’oko Re

2 cr Ooko Re n’igbala ,
Ti nwa lati mo,
mf Iye, alafia l’oko Re.
At’ ife ailopin.

3 mf Ki se ni gberaga,
Tab’anife tooto
L’a ya kuro l’ona t’eda
T’a wa pade nihin.

4 A wa gba or’ofe
T’o fi fun wa l’ofe
cr Apejo l’aye n’tori Rre.
K’a le pejo l’orun.

5 A mo p’O wa nihin.
cr Sugbon f’ara Re han.
Oluwa , jeki gbogbo wa
Mo itunu nla Re.

6 p K’hun isoji Re.


Pa oku ese run.
cr Si mu okan wa yo de ‘nu,
N’ireti ‘fe pipe.
Amin
931
S.M
Alafia mi ni mo fi fun yin Jn.14:27

1 mp A o pinya l’ara lo
S’oniruru ilu
mf Sugbon awon ore Jesu
Wa n’isokan emi.

2 Jesu , Olori wa.


L’O da okan wa po.
Awa t’o a mba rin ni mimo
L’O so d’okan l’emi.

3 cr Jek’ a te siwaju
Ninu ise Jesu.
K’a ma tele Olusegun.
K’a ba le segun si.,

4 mf Ogba Oluwa mbe.


Niwaju On ‘se Re
Awa si now ere nla na.
Tti a nlo ba loke.

5 cr K’ife at’ ere wa


Ggoke nigbagbogbo.
Lati d’ebute simi ni.
Nibiti se wa pin.

6 Nibe n’ise wa tan


Iya oun ‘rora wa
L;’ebute ayeraye ni.
Aki yoo pinya mo.

7 Ilu alafia,
Tt’awon mimo pade
mf Nibe l’ao r’oju ara wa.
T’ao yo mo ara wa.

8 T’awa –t’ijo saju


L’ao jumo gba ‘bukun,
Ninu ayo l’ao tun wo.
Isimi ailopin .
Amin
932
6.6.8.4
Ki Oluwa alafia tikarare , ma fun yin ni alafia nigbagbogbo ,II Tes.3:16

1 mp O ro alafia
L’a fi sin yin , ara
cr k alafia bi odo nla
Ma ba yin lo.

2 mp N’nu oro adura,


Af’awon ara wa.
Le iso Oluwa lowo,
Ore tooto,

3 mf Oro ife didun


L’a fi p’odigbose,
Ife wa ati t’Olorun
Y’o ba won gbe.

4 f Oro ‘gbagbo lile


Ni igekele wa.
Pe, Oluwa y’o se ‘ranwo
Y’o so ayo t’o le dun ju
Nigba gbogbo.

5 Oro reti didun


Y;o mu ‘pinya wa dun
Y’o so ayo t’o le dun ju
Ayo t’aye

6 mf O digbose ara.
N’ife ati ‘gbagbo
P Tit’ao fi tun pade l’oke
N’ile l’orun .
Amin
933
C.M
O mu won wa si wa si ebute ife won. OD.107:30

1 mf Olorun so wa n’nu oko


Larin omi jinjin,
S’oluso wa ba ti nwa lo,
Ninu ajin oru.

2 Eru ko ye ki o ba wa.
Larin iji ti nja,
Niwon gba t’o wa nitosi

3 Iparoro ati Iji,


T’o nkoja lori le.
Iwo ni o da gbogbo won.
Won wa nikawo Re.

4 Nigbati ‘awon Aposteli ,


Wa lori’gbi okun ,
Ase kan lat’ odo Re wa.
Mu dake roro wa.

5 mp Gbati iji to buru ju.


Ba nru l’atokan wa.
Oluwa ma sai ba wa gbe.
F’alafia ba wa gbe.

6 mf Ninu wahala aye yi,


Ma se amona wa,
Titi ao fi de le rere,
Nibi t’ese ko si.
Amin
934
7.7.7.7
Ki Oluwa ki o so tempitire nigbati a o ya kuro lodo ara wa.Gen.31:49

1 mf Ni akoko ipinya
Jeki a fi ara wa.
S’abe oju at’ okan
Ore korikosun wa.

2 p Jesu gbo adura wa.


‘Wo ti nso agutan Re.
K’adun atioju Rre.
Pa gbogbo okan wa mo

3 mf K’a l’agbara n’ipa Re.


F’adun s’irora gbogbo,
K’o si da emi wa si.
Titi ao fi tun pade.
Amin
935
10.10.10.6
Ati opolopo ninu awon ti o sun ninu erupe ile ni yio ji, awon miran s’iye anipekun, Dan

1 mf Ma sun, olufe; k’o sima simi


Gb’ ori re le aya Olugbala
A fe o sugbon Jesu fe o ju.
p Sun ‘re, sun ‘re, sun re.

2 mf Orun re dun bi orun omode,


Iwo ki yo si ji si ekun mo.
Isimi t’o daju n’ismi re.
p Sun ‘re, sun ‘re, sun re.

3 f Tit’ ao ka okunkun aye kuro


Tit’ ao fi ko ikore ‘wole
Tit’ oye aye yio fi la,
p Sun ‘re, sun ‘re, sun re.

4 mf Tit’ orun ajinde y’o fi yo


T’awon oku n’nu Jesu y’o dide
On y’o si wa ninu olanla Re.
Sun ‘re, sun ‘re, sun re.

5 mf Tit’ ewa orun y’o je tire


cr Ti iwo o ma ran ninu ogo
f Oluwa y’o de o l’ade wura.
p Sun ‘re, sun ‘re, sun re.

6 mf O d’owuro sa ni, olufe mi.


A tun fere ri ra na: nibiti
di Ipinya ati ituka ko si.
p Sun ‘re, sun ‘re, sun re.

7 mf Tit’ ao fi pade niwaju ‘te Re.


Nin’aso igunwa awon Tire.
Tit’ ao mo gege bi a ti mo wa.
p Sun ‘re, sun ‘re, sun re.
Amin.
936
7.7.7.7
O si wi fun u pe ma sokan mo.Lk’7:13

1 p ‘Gbat’ a kun fun ‘banuje ,


‘Gb’omije nsan l’oju wa.
Gbat’ a nsokun t’a nsofo,
cr Olugbala gbo ti wa.

2 p ‘’Wo ti gbe ara wo,


O si mo ‘banuje wa.
O ti sokun bi awa .
cr Olugbala , gbo ti wa.

3 pp ’Wo ti teriba fun ‘ku.


Wo ti t’eje Rre sile.
A te o si posi ri.
cr Olugbala , gbo ti wa.

4 p ‘Gbati okan wa ba baje.


Nitori t’a da.
Gbati eru ba okan wa.

5 p Wo ti mo eru ese.
Ese ti se gbe.
Eru ese na l’o gbe.
cr Olugbala ,gbo ti wa.

6 f O ti silkeun iku
O ti setutu f’ese.
ff O wa lowotun
cr Olugbala , gbo ti wa.
Amin
937
L.M
Won wo inu alafia won simi lori akete won. Isa 57:2

1 mp Igba asale ti dun to.


Ti ara tu ohun gbogbo,
‘Gbati itansan orun ale.
Ba ntan mole s’ohun gbogbo.

2 Beni’keyin onigbagbo,
On a simi l’alafia ;
cr Igbagbo t’o gbona janjan.
A mole ninu okan re.

3 mp Imole kan mo l’oju Re.


Erin si bo ni enu re.
O nf’ede t’ahon wa ko mo,
Soro ogo t’o sunmo’le.

4 cr Itansan ‘mole t’orun wa.


Lati gba ni ‘yanju l’ona.
Awon angeli duro yi ka.
Lati gbe lo, s’ibugbe won.

5 mp Oluwa je k’a lo bayi,


K’a ba O yo, k’a r’oju Re.
Te aworan Re. S’okan wa.
Si ko wa b’a ti ba O rin.
Amin
938
7.7.7.7
Li owo Re ni mo fi emi mi le OD.31:5
1 mp Lala alagbase tan.
Ojo ogun ti pari.
cr L’ebute jinjin rere.
Ni oko re ti gun si,
Baba l’abe itoju Re.
L’awa f’iranse Re yi si.

2 mf N’ibe l’a re won l’ekun


Nibe, won m’ohun gbogbo.
di Onidajo ododo
Ndan se aye wo nibe.

3 mf Nibe l’olus’agutan
Nko awon agutan lo,
di Nibe l’o ndabobo won,
Koriko ko le de’be.

4 mp Nibe l’awon elese,


Ti nteju m’agbelebu
cr Y’o mo ife Kristi tan
L’ese Re ni paradise

5 mf Nibe l’agbara Esu


Ko le b’ayo won je mo,
Kristi Jesu sa nso nwon
On t’o lu fun’ dande won.

6 pp ‘Erupe fun erupe’


L’ede wa, nisiyi;
A te sile lati sun.
cr Titi d’ojo ajinde .
Amin.
939
D.S.M
O seun , iwo omo –odo rere ati olotito ---- bo sinu ayo Oluwa re.Mat.25:21

1 mp ‘Rranse Olorun , seun.


Simi n’nu lala re;
mf Iwo ti ja , o si segun,
Bos’ayo Baba re.
Ohun na de loru,
O dide lati gbo,
P Ofa iku sai wo, l’ara
pp O subu , ko beru.

2 f Igbe ta loganjo,
‘Pade Olorun re.
O ji , o ri Balogun re.
N’n’adura on ‘gbagbo,
cr Okan re nde wiri,
O bo amo sile.
Gbat’ile mo, ago ara.
p Si sun sile l’oku.

3 f Rora iku koja,


Lala at’ ise tan.;
Ojo ogun jija pari,
Okan re.r’alafia.
f Omo-gun krist’ o seun
Ma korin ayo sa.
ff Simi lodo Olugbala .
cr Simi titi aye.
Amin
940
6.6.6.6.
Ibukun ni fun oku ti o ku nipa ti oluwa .Ifi 14:13

1 p Ibukun ni f’oku
T’o simi le Jesu.
Awon t’o gb’ori won.

2 mf Iran ‘bukun l’eyi


Ko si b’oju l’arin,
Won ri Eni mole
Ti won ti fe l’airi.

3 Won bo lowo aye.


Pelu aniyan iji ki ja,
Won bo lowo ewu
T’o rin l’osan l’oru.

4 mp Oluso’Agutan
Nibit’ iji ki ja,
Mu won lo si papa
L’eba omi iye.

5 Lor’ iboji won.


L’awa nsokun loni
Won j’en’ ire fun wa.
T’a ki y’o gbagbe lae.

6 mp A k’y’o gb’ohun won mo,


Ohun ife didun
Lat’ oni lo’aye.
Ki o tun mo won mo.

7 cr Eyin oniure.
E fi wa sile lo,
f A o sokun yin titi
ff Jesu pa sokun ri.

8 Sugbon a fe gb’ ohun


Olodunmare na;
Y’o ko, si wipe ,
Ejinde , e si yo,;
Amin
941
L.M
Ranti Eleda nisiyi li ojo ewe re. A. oni 12:1

1 A ko ni ‘bugbe kan nihin,


Onile e rora yanyan;
B’o fi gbogb’ aye ko Garet,
` Ese mefa ni bussun wa.

2 A ko ni’bugbe kan nihin.


Or’aye fowoba fi le.
Ni hooho la sa w’ aye
Ni hooho lao pada lo,

3 A ko ni’bugbe kan nihin.


O ko gbagbo p’ajo l’o wa
Lo wo ‘boji w’awon to sun,
Awon ni won de’ibi simi.
Amin
942
L.M
Adorin odun ni iye ojo odun wa.
OD.90:10

1 mf Olorun lat’ irandiran ,


‘Wo n’isimi at’ abo wa.
K’a to da orun at’ aye,
Giga ni ife Re l’oke.

2 mf O ti nkoba k’igba to wa ,
tabi k’a lo to da eniyan ;
Ijoba Re y’o wa laelae,
Gbat’ igba at’ aye ba pin .

3 mf Iku ,bi odo , ngba wa lo,


Aye wa bi itan lasan ,
O dabi itanna owuro,
Ti a ke lu ‘le t’o si ro,

4 mf Jek’ amo ailera eda


K’O sun ojo wa siwaju
p Tit’ ao fi mura de iku,
Nipa ‘wenumo or’ofe .
Amin
943
7.6.7.7.6
Goke Jordani Jos 3:17

1 mf A won ti gun s’ebute,


p Loke orun; Loke orun;
mf Ebi ko ni pa won mo,
Won bo lowo irora,
f Loke orun ;Loke orun.

2 A won ko wa fitila ,
p Loke orun; Loke orun
Mole ni l’ojo gbogbo,
Jesu si n’imole won,
f Loke orun’ Loke orun.

3 A wura n’ita won je,


p Loke orun’ Loke orun;
Ogo be si po pupo ,
Agbo Jesu ni won je.

4 A tutu ki mu won,
p Loke orun; Loke orun;
Owore won ti koja ,
Gbogbo ojo l’odara;
f Loke orun; Loke orun.

5 A won dekun ija ja.


P Loke orun ;Loke orun;
Jesu l’o ti gba won la ,
T’awon Tire l’o si nrin.
Loke orun ; Loke orun.

6 A won ko ni sokun mo,


p Loke orun; Loke orun;
Jesu sa wa lodo won,
Lodo Re ni ayo wa.
f Loke orun; Loke orun;

7 A a o dapo mo won ,
p Loke orun ;Loke orun
A nreti akoko wa,
f Gba Oluwa ba pe ni
di S’oke orun S’oke orun.
Amin
944
L.M
Emi nku li ojojumo , I Kro 15:31

1 mp Bi agogo ofo t’a nlu,


Ti npe okan yi koja lo,
K’olukuluku bi ra re.
‘Mo ha setan b’iku pe mi.

2 mp Ki nf’ohun ti mo fe sile.
Ki nlo sid’ite idajo,
Ki ngbohun Onidajo na.
Tti y’o so ipo mi fun mi,

3 p Ara mi ha gba , b’o wipe,


‘Lo lodo mi eni egun
cr Sinu ina t’a ti pese
Fun Esu ati ogun re?

4 f Jesu Oluwa , jo gba mi,


Iwo ni mo gbekele mi le.
Ko mi ki nr’ ona ewu yi,
Ko mi ki mba O gbe titi.
Amin
945
C.M
Ni kutuku o li awo lara , o si dagba soke , li asale , a ke lule o si ro, OD.90:6

1 p I tana t’o bo ‘gbe l’aso,


Tt’o tutu yoyo be,
cr Gba doje ba kan , a si ku,
A subu , a si ro,

2 A pere yi ye f’ara wa,


B’or’ Olorun ti wi,
K’omode at’ agbalagba
P Mo, ra won l’eweko

3 p A ma gbekele wmi re.


Ma pe ‘gba re ntire ;
cr Yika l’a nri doje iku.
O mbe ‘gberun lule.

4 Eyin t’a dasi di oni,


p Laipe , emi y’o pin,
f Mmura k’e si gbon l’akoko ,
K’iko iku to de.

5 Koriko b’o ku ki ji mo;


E ku lati tun ye;
P A b’iku lo je ‘lekun nko,
S’irora ailopin .

6 f Oluwa ,je k’ a jipe Re ,


K’a kuro n’nu ese;
Gbat’ a lule bi koriko ,
K’okan wa yo si O,
Amin
946
S.M
Sisun li o sun.Lk.8:52

1 mf O sun , ni Jesu wi;


Nipa ti Lasaru
Eni t’o ku, ti a ti sin,
T’a ti te s’ iboji,

2 di Oku ojo merin


Sun ni, loju Jesu.
cr On l’Ajinde ati Iye
Fun awon t’o gba gbo.

3 mf Ore Jesu ki ku,


Won a ma parada ,
Kuro ni kokoro ile
S’ohun ti nfo l’oke.

4 di Sun , ara, olufe,


Jesu duro ti o,
cr Ma foya , o ti seleri
Ajinde f’eni Re.

5 mf O fere gb’ ohun na,


Lat’ oju orun re,
Ohun didun Jesu ti y’
Pe o si ajinde .

6 cr A ko ni baraje
Bi alainireti,
Od’ owuro l’a o ki o,
Sun re, ara, sun re.

7 mp Awa pelu y’oo sun


Li akoko ti wa.
cr A k’ile mo ba gbogbo wa
L’ese Olugbala .
Amin
947
P.M
Emi yio si pada to Olorun ti o fi I funni. A. Oni 12:7

1 mp Ara , iwo si / waju wa lo,


Emi re mi./ mo si ti fo lo,
Sibiti ko ni /s’ekun mo;
Ti / ko irora .

2 O bo lowo / eru ara


Ati lowo /aniyan aye.
di Nib’eni-burubu / ye yonu.
p Ti a / lare si simi.

3 mp Wo lasaru / ajo l’o si sun.,


O ti / gb’ agbelebu re.
cr Krist ti fi ese re/ le ona ,
` Lati / de ib’isimi.

4 mp Bi Lasaru / l’o si sun,


L’a / kaya Baba re.
di Nib’ eni-buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si isimi.

5 mf Ese ko le / ba o je mo,
I / yemeji d’opin;
Igbagbo re ni / nu Kristi
At’ Emi / ko ni ye mo lae

6 L’orun lohun / n’iwo o ba


Awon ore / t’o ti lo saju;
di Nib’ eni-buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si simi

7 Alufa ti wi ni / sisiyi pe,


mp Eru f’eru e / rupe f’erupe;
Awa si ko e / s’ori re.
A si / sami s’ori re.

8 cr Sugbon emi re / ti o fo lo,


So / do awon mimo;
di Nib’ eni –buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si simi.
9 mf Gbat’ olu / wa ba si pe.
A / wa t’o ku lehin;
Oluwa wa/ awa be O,
K’a / ye lodo wa je,

10 K’oluluku wa, b’a / ra wa yi,


Le ri / / aye lodo Re.
di Nib’ eni –buburu / ye yonu,
p Tia / lare si simi.
Amin
948
S.M
Awon emi, nipa igbagbo ati suru, li o jogun ileri wonini Heb.6:12

1 mf F’awon eniyan Re.


T’o ti f’ aye sile;
Awon t’o mo O, to sin O,

2 F’ awon eniyan Re.


Gba ohun ope wa,
Won ku n’igbagbo, Re.

3 mf Ni gbogbo aye won.


‘Wo ni won now loju’
Emi Mimo Re l’o esan won.
Lati s’ohun gbogbo.

4 f Fun eyi, Oluwa .


cr A nyin oruko Re.
Je a tele iwa won.,
di Ki a le ku bi won.
Amin
949
10.10.10.4
A fi awoosanma eleri pupo yi wa ka Heb.12:1

1 mf F’awon eniyan Re t’o lo simi;


Awon ti o fi gbagbo jewo Re.
f K’a yin oruko Re, Olugbala Aleluya

2 Iwo l’apata won at’ odi won ,


Iwo ni Balogun won l’oju ja.
cr Iwo ni imole okunkun won.Aleluya

3 mp Je ki awon om’ ogun Re l’aye


cr Jagun nitoto b’awon ti gbani;
f Ki won le gba ade ogo bi won Aleluya

4 mf Idapo ibukun wo l’o to yi,


cr Awa nja ihin, awon nyo l’ohun;
f Be tire kanna l’awa at’ awon –Aleluya.

5 mf Gbat’ ija ba ngbona , ti ogun nle,


p A dabi eni ngb’ orin ayo won ;
cr Igboya a de, at, agbara .Aleluya.

6 p Ojo nlo, orun wa fere wa fere wo na,


Awon ajagun toto y’o simi,
Didun ni simi paraise Aleluya.

7 f Leyin eyi, ojo kan mbo,


Awon mimo y’o dide n’nu ogo
Oba ogo yio wa larin won –Aleluya;

8 ff Lat’ opin lat’ opin okun,


Ogun logo nro wo’bode pearli
Won nyin Baba , omo ati Emi-Aleluya.
Amin
950
8.7.8.7.D
Ohun ogo li a nso ni tire , iluOlorun .OD.87:3

1 f Ohun ogo Re l’a nroyin


Sion, ti Olorun wa.
Oro Eni t’a ko le ye.
Se o ye fun ‘bugbe Re.
‘Pile re mbe lor’ Apata.
Kini , le mi simi re?
A f’odi gbala yi o ka.
K’o le ma rin ota re.

2 mp Wo omi ‘ye ti nsan lati.


Isun ijinle ‘fe wa.
O fun gbogbo omo re.
Eru aini ko si mo,
Tal’ o le re’ gba odo na.
Ba nsan t’o le pongbe re?
Or-ofe Olodunmare
Ki ye lat’ irandiran.

3 cr Olugbala , b’O ba ka mi,


Kun awon ara Sion
B’aye nkegan, t’o si nsata,
Un o f’itiju na s’ogo ;
p Sisa l’ohun afe aye.,
Pelu ogo asan re.
f Isura toto at’ ayo,
Kik’ omo Sion l’o mo .
Amin
951
7.5.6.6.7.7.7.7.
Ninu ile baba mi, opolopo ibugbe lo wa. Jn.14:2

1 f Ile ailopin kan wa.


T’o ndan , t’o dara ;
Nnib’ ayo pipe wa,
Ko si oru nibe,
Awon Aneli si nkorin
Nigbagbogbo yi te ka ;
cr Nigbawo ni un o ri o,
Ile didan , didan yi;
ff Ile didan yi.
Ile Mimo yi.
Ile igbala wa.
Ibugbe ogo.

2 mf Itanna didun wa n’be,


N’ile didan yi,
Awon omode nko
Orin iyin Jesu.
f A b’ orin na ti dun to,
Won y’ite funfun na ka;
Nigbawo ni un o ri o,
Ile didan , didan,

3 cr Laipe ngo dapo mo won.


Ni oke orun.
mf Kristi ni gbala mi.
Ese ti un o beru .
f B’ o ti joko lor’ ite.
‘Gbana emi o ri o
Ile didan , didan yi,
Amin
952
8.7.8.7
Olorun yio si nu omije gbogbo nu kuro li oju won.Ifi.21:4

1 mf I banuje ko si, l’orun ,


Beni ko si ipinya
cr Ekun awon ta ti dariji ;
Ibanuje ko si ni’ lu na,
Beni ailera ko si,
f ‘Tori gbogbo ilu na je imole
‘Tori ekun ko si l’orun

2 mf Aisedede ko si nibe,
Ko s’oju t’o n’onije
‘Tori itelorun y’o wa,
ekun ki y’o si l’orun

3 cr Ko si ‘robinuje l’oke,
Ko si si ini-edun,
A ki y’o s’oro kikoro,
Ekun ki ‘o si l’orun

4 di ‘Banuje kun okan nihin,


‘Tori ipinya ti mbe;
mf Sugbon ayo l’o wa l’ohun,
Ekun ki y’o si l’orun
Amin.
953
15.11.15.11.&.Ref.
Nitori ipe yio dun, a si ji awon oku dide,

1 mf ‘Gbati ipe Oluwa da dun, t’aye y’o si fo lo,


Ti imole ojo titun y’o si de;
Nigbati awon omo igbala ba pejo l’oke,
T’a ba si p’oruko ;’ohun, un o wa n’be
f ‘Gbat’ a ba p’oruko l’ohun,
‘Gbat’ a ba p’oruko l’ohun,
‘Gbat’ a ba p’oruko l’ohun,
cr Nipa ore-ofe nikan, un o wa n’be,

2 mf l’oro ojo na t’awon oku n’nu Kristi y’o jinde,


Ti won y’o si pin n’nu ogo ajinde;
‘Gbati awon ayanfe y’o pejo si ode orun,
T’a ba si p’oruko ;’ohun, un o wa n’be

3 cr Jeki a fi gbogbo akoko wa sise f’Oluwa


Jeki a royin ife iyanu Re;
Nigbati a ba si pari ire ije wa l’aye,
mf T’a ba si p’oruko l’ohun, un o wa n’be.
Amin.
954
10.10.10.10.
Lati isisiyi lo, a fi ade ododo lele fun mi. II Tim, 4:8

1 cr ‘Gbati ‘ise on’danwo mi ba pari


Ti mo si gun s’ebute rere na;
Ki nsa le sunm’Oluwa ti mo fe
Eyi y’o je ogo fun mi titi
mf Eyi y’o je ogo fun mi
Ogo fun mi, ogo fun mi,
Ti un o w’oju Re nipa or’ofe,
Eyi y’o je ogo fun mi.

2 mf Nigba ore ofe Re ailopin


Ba fi ipo kan li orun fun mi,
cr Ki nsale wa n’be lat’ w’oju Re
Eyi y’o je ogo fun mi titi,

3 mf Ore ti mo fi fe y’o wa nibe;


Ba fi ipo kan li orun fun mi,
f Mo mo pe un o r’ayo lodo Jesu
Eyi y’o je ogo fun mi titi.
Amin.
955
15.15.15.15.&.Ref.
O si si fi orin titun si mi li enu, ani orin iyin si Olorun wa. OD. 40:3.

1 f Orin mbe li orun, iru eyiti awa ko mo


Nibiti awon angeli nkorin ‘yin s’Odoagutan
Harpu won ni ohun didun, won si dun pelu,
A! ki awa le se ‘bi ti won lati sin Oluwa,
ff Mimo, Mimo, l’awon angeli nko,
Mo si ni ‘reti lati ba won korin li orun,
cr Sugbon won ko leba mi korin ti irapada
N’tori angeli ko mo ayo ti ‘gbala mu wa.

2 mf Sugbon mo gbo orin miran ti a ko l’ohun oke


Si eni t’Ora wa pada t’O si gba wa, l’orun na;
f Awa ti la iponju wa ja si ile didan y,
Nibi orisun ‘ye nsan l’O ti fo aso wa mo

3 di Awon angeli dake, n’tori won mo le korin na,


f Bi rio omi pupo l’enu awon t’a f’eje ra!
N’tori won nso ti isegun lori ‘danwo at’ija,
ff Won si nyin Olurapada ti O ti wipe, “O seun”.

4 f Bi eni ko tile nse angeli, mo mo pe l’ohun


Un o b’awon mimo korin t’awon angeli ko ni ko
ff Un o korin ti Olugbala ti O ku ni Kalfari
Lati dari ese mi ji mi, lati da mi sile.
Amin.
956
15.15.15.14.&.Ref.
O si fi ilu nla han mi Jerusalemu mimo; Ifi. 21:10

1 Ile alafia kan wa, ti ‘lekun re si sile,


Eni ti okan re funfun, ti o si mo, y’o gbe ‘be,
K’ise enu ona ogo nkan l’a ni ba wo ‘le
cr Sugbon eni ti y’o wo ‘be yo k’ese sile na
di Wa nihin, wa nihin si ‘le eletu-loju
Ko s’ohun t’a le fi we adun mimo ti o wa nibe;
mf Wa nihin, wa nihin, fi asale yi sile,

2 Irugin orun nhu nibe, ni ‘le re ti o l’


mf O si nhu igi ajara ti o ntu okan lara;
Oke giga, didan wa n’be t’o je ibi itura,
Abo t’o daju ni o je f’okan sunmo O.

3 cr Tani ko fe lo s’ile na t’o fe joko s’asale


‘Gbati eso ile na pon, ti ‘be si wa nitosi?
mf Nje fi ayo wo ile, n’tori Oluwa mbe fun o.
Niwaju ‘te ogo Re, ni ‘wo o ma gbe titi.
Amin.
957
7.6.7.6.7.6.&.Ref
O ti pese ilu nla kan sile fun won.Heb. 11:16

1 cr Ni’ le ti ojo ki nsu.


N’ilu Olorun wa;
Ilu na y’o wa titi,
Ko si ‘oru nibe,
mf Baba y’o omije nu,
Ko s’iku, rora eru
Ko si kika akoko
Tori ko s’ oru n’be.

2 mf Enu ona re je Pearl,


N’ilu Olorun wa;
Ita re si je wura.
Ko s’oru nibe.

3 A ki nti enu ona


T’ilu Olorun wa;
Omije ‘ye nsan nibe.
Ko si s’ oru nibe.

4 cr Won ko fe ‘tansan orun


Nn’ilu Olorun wa;
f N’tori krist’ n’imole re.
Ko si s’oru nibe.
Amin
958
11.11.11.11.
Eni ti o ba segun ni y’o jogun nkan wonyi. Ifi.21:7

1 I le ewa wonni b’o ti dara to,


Ibugbe Olorun t’oju ko ti ri;
Tal;’ o fe de ibe , leyin aye yi?
Tal’ o fe k’a wo on ni aso funfun.

2 p Awon wonni t’oji ninu orun won.


Awon t’oni gbagbo si nkan t’a ko ri;
Awon t’o k’aniyan won l’Olugbala ,
Awon ti ko tiju agbelebu Krist’

3 cr Awon ti ko nani gbogbo nkan aye.


Awon t’o le soto de oju iku.
Awon t’o nrubo ife l’ojojumo,
Awon t’o f’igbala Jesu rapada.

4 f Itiju ni fun yin, Om ‘ogun Jesu.


Eyin ara ilu ibugbe orun.
Kinla e nfi fere at’ ilu sire
‘Gbat’ o ni k’e sise t’o si pe ‘E ja.

5 cr B’igbi omi aye si ti nkolu wa.


Jesu Oba Ogo so si wa l’eti;
Adun t’o wa l’orun ilu mimo ni.
`Nibit’ isimi wa , lae ati laelae.
Amin
959
6.6.6.D
Ninu ile Baba mi opolopo ibugbe lo wa Jjn. 14:2

1 mf Ile ‘bukun kan wa.


Leyin aye wa yi.
Wahala irora,
At’ekun ki de ‘be.
cr Igbagbo y’o d’opin,
Ao de reti l’ade,
f Imole ailopin
Ni gbogbo ibe je.

2 mf Ile kan si tun mbe


Ile alafia
cr Awon Angeli rere
Nkorin n’nu re laelae ;
ff Yi te ogo egbe mimo
L’awon t’o ri Jesu
Nwole , won nteriba
F’eni Metalokan.

3 mf Ayo won ti po to.


p Awon t’o ri Jesu,
cr Nibt’ o gbe gunwa.
T’a si nfi iyin Re.
Ati t’isegun Re.
Won ko dekun royin.
Ohun nla t’o ti se.

4 mf W’oke, eyin mimo,


E le iberu lo.,
p Ona hiha kan na.
L’Olugbala ti gba;
cr E fi suru duro
Fun igba die sa.
f T’ erin –t’ l’on o
Fi gba yin s’odo Re.
Amin
960
L.M
Baba , emi fe ki awon ti iwo fifun mi, ki o wa lodo mi, nibiti emi gbe wa.Jn 17:24

1 mf Jeki m’ ni po mi l’odo Rre.


Jesu Iwo isimi mi.
Gbana l’okan mi y’o simi,
ff Y’o si ri ekun ‘bukun gba,

2 mf Jeki m’ni po mi l’odo Re.


K’emi k’o le ri ogo Re.
Gbana ni okan etan mi.
Yoo ri f’ara le.

3 mf Jeki m’ ni po mi l’odo Rre.


Nnibi awon mimo nyin O,
Gbana ni okan ese mi.
Y’o dekun ese ni dida.

4 mf Jeki m’ ni po l’odo Re.


Nibi a ki y’ipo pada.
ff Titi aye titi aye.
Amin
961
L.M
Aa wa ti Olori Alufa nla kan ti o ti koja lo sinu awon orun.Heb 4:14

1 f Olor’ Alufa giga kan,


T’o gba’ eda wa wo f’arahan
Nnibi ti tempili orun wa.
Ile ti a ko f’ owo ko,

2 p On bi Oni gbowo eniyan


T’o t’eje yebiye s’ ile.
T’o npari se nla Re l’orun ;
Olugbala , ore eniyan .

3 mf B’o tile g’oke lo s’ orun


Oo nf’ oju ife wo aye
Eni t’o je oko eniyan
O mo ailera eda wa.

4 mp Alabajiya wa si mo,
Bi rora wa si ti po ti,
di L’orun , O si ranti sibe.
pp Omije on waya ja Re.

5 mp Ninu ibanuje okan ,


Eni ‘banuje pin n’nu Re.
cr O mba wa daro edun wa.
O si ran ojiya lowo,

6 f K’ak’edun wa lo’s’odo Re.


Pelu ‘gboya , nibi ite
K’a toro yo wa nigba ibi.
Amin.
962
C.M
O si fi ilu nla han mi Jerusalemu mimo.Ifi. 21:10

1 Jerusalemu, bi ayo,
Tt’o se owon n’ise fun mi,
cr Gbawon’ise mi o pari
L’ayo l’alafia .

2 mf Gbawo ni oju mi y’o ri.


Enu ‘bode pearl re.
Odi Re t’o le fun ‘gbala,
Ita wura didan

3 Ogba ti o ju Eden lo,


Ibi ko si ni be.
cr Ilu ayo, mo nlepa re.
Larin iji aye.

4 mf Ese t’emi o ko iya,


Iku ati iponju
f Mo now ile rere Kenan’
Ile mole titi.

5 Aposteli , martayr, woli


Won y’Olugbala ka’
Awa tikarawa fere.
Dapo mo ogun na.

6 mf Jerusalemu , ilu ayo,


Okan mi nfa si o;
`cr Gbati mo ba ri ayo re.
Ise mi y’o pari.
Amin
963
6.6.6.6.8.8
Sugbon nisisiyi won nfe ilu kan ti o dara ju be lo. Heb 11:16

1 mf Jerusalemu t’ orun
L’orin mi, ilu mi.
Ile mi bi mba ku.
Ekun ibukun mi,
Ibi ayo
Nigbawo ni.
Un o r’oju Re.
Olorun mi.

2 mf Nibe l’oba mi wa.


p T’a da l’ebi l’aye ;
f Angeli nkorin fun.
Won si nteriba fun.

3 Patriark igbani ,
Par’ ayo won nibe.
Awon woli , won now.
Omo Alade won.

4 mf Nibe ni mo le ri.
Awon Aposteli ;
At’ awon akorin.
Ti nlu harpu wura.

5 mp Ni agbala wonni,
Ni awon Martir wa.
cr Won wo aso ala.
Ogo bo ogbe won.

6 p T’emi yi sa su mi,
Tit’mo ngb’ ago Kedar’
Ko si r’yi loke,
Nibe ni mo fe lo.
Amin
964
6.4.6.4.6.7.6.4
Awa si nlo ibiti Oluwa wipe emi o fi fun yin Iwo ba kaloNum.10:29

1 mf Ile ayo kan wa.


Tti o jina;
Ni b’awon mimo wa.
Won nran b’orun;
cr A won nkorin didun
Ki iyin Re ko ro.
f Yin ,Yin laelae.

2 mf Wa sile ayo yi,


Wa, wa k’a lo,
E se nsiyemeji
E se nduro
Ao wa l’Alafia
cr A o ba O joba ,
L’ayo laelae.

3 f Oju gbogbo won ndan


N’ile ayo,
p N’ipamo Baba wa.
Iife ki ku.
p Nje sure lo s’ ogo
ff Gba ade at’ ijoba
Tt’o mo ju orun lo,
Joba titi.
Amin
965
D.S.M
Beli awa o si wa lae lodo Oluwa I Tes.4:17

1 mf ‘Lae lodo Oluwa’


Amin, beni kori,
cr Iye wa ninu oro na.
Aiku ni titi lae.
mp Nihin ninu ara.
Mmo s’ako jina s’I;
cr Sibe alare ni mo nfi
Ojo kan sunmo’ le.

2 mf Ile Baba l’oke


Ile okan mi ni;
Emi nfi oju igbagbo
Wo ‘bode wura re.
p Okan mi nfa pupo
S’ile na ti mo fe
cr Ile didant’ awon mimo.
Jjerusalemu t’orun.

3 di Awosanama dide.
Gbogbo ero mi pin.
Bi adaba Noa, mo nfo,
Larin iji lile.
cr Sugbon sanama kuro,
Iji si rekoja
Ayo ati alafia.
Si gba okan mi kan.

4 mf L’oro ati l’ale ,


L’osan ati l’oru
Mo ngbo orin orun bori
Runduru aye.
ff Oro ajinde ni.
Hiho isegun.ni.
Lekan si, lae l’od’ Oluwa
Amin., beni k’o ri.
Amin
966
C.M.&Ref.
Mo ni ife lati lo ki emi wa lodo Kriti.Fili 1:23

1 f P aradise, paradise,
Ttani ko fe ‘simi,
Tani ko fe’ le ayo na.
Ile alabukun .
Nib’ awon oloto
Wa lae ninu ‘n\mole
Won lae nigbagbogbo
Niwaju Olorun.

2 f Paradise paradise.
Aye ndurogbo lo.
Tani ko si fe lo simi.
Nib’ ife ki tutu.

3 f Paradise paradise
p Mo fe ki nye d’ese
Mo fe ki nwa lodo Jesu.
Li ebute mimo.

4 f Paradise paradise
Uun ko ni duro pe mo.
Nisiyi b’enipe mo ngbo
Ohun orin orun.

5 f Jesu Oba paradise


Pa mi mo n’nu fe Re.
Mu mi de ile ayo na ,
Nib’ isimi l’oke.
Amin
967
8.9.8.8
Nitori ti o pese ilu kan sile fun won Heb.11:16

1 mf A nsoro ile ‘bukun ni,


Ile didan at’ ile ewa.
‘Gbagbogbo l’a nso t’ogo re.
p Y’o ti dun to lati de be.

2 mf A nsoro ita wura Re.


Oso odi re ti ko l’egbe,
‘Faji re ko se f’enu so
p Y’o ti dun to lati de be,

3 f A nso p; ese ko si nibe.


Ko s’aniyan at’ ibanuje,
Pelu ‘danwol’ode , ninu;
p T’o ti dun lati de be,

4 f A nsoro orin iyin re.


Ti a kole f’orin aye we.
di B’o ti wu k’orin wa dun to.
p Y’o ti dun to lati de be,

5 f A nsoro isin ife re.


Ti agbada t’awon mimo nwo.
Ijo akobi ti oke;
p Y’o ti dun to lati de be.

6 mp Jo Oluwa l’onakona,
Sa emi wa ye fun orun.
cr Laipe awa na yio mo,
B’ o ti dun to lati de be,
Amin
968
7.6.7.6.
Aawa ko ni ilu ti o duro pe nihin awa nwa ti mbo ,Heb.13:14

1 p Kukuru l’ojaye wa,


Die l’ojo aro
cr Aye ti ko lopin mbe.
Nibit’ ekun ko si.

2 mf L’aye wo lo to yi.
Isimi ailopin ,
At’ ile nla t’o dara
F’elese bi awa.

3 cr L’aye yi awa njagun,


Lorun , ao d’gbekele,
Ade ti ki dibaje,
Ti yo ma dan titi.

4 mf Nibe l’awa o gbe ri.


Eni t’a gbekele ,
Iye awon t’o ba mo,
Ni yio je tire.

5 cr Owuro ojo na mbe.


Okunkun y’o ka lo,
f Awon olokan pipe,
Y’o ma ran bi orun.

6 ff Olorun at’ ipin wa,


N’nu ekun ore re.
Nibe ni ao ma wo O,
Ao yin lojukoju.
Amin
969
8.8.6.D
Aawa nyo ni ogo Olorun Rrom 5:2

1 mp Leyin aye buburu yi.


p Aye ekun on osi yi,
Ibi rere kan wa.
Ayida ko si nibe,
Ko s’ oru f’osan titi.
p Wi mi ‘wo o wa nibe?

2 mf Lekun ogo re ti m’ese,


Lati b’iberu sin Oluwa,
T’won ko nsaani aye;
Awon t’a f’ Emi mimo to,
Awon t’o nrin l’ona tooro,
f Awon ni o wa nibe,
Amin.
970
8.9.9.9.&Ref
Ile rere na ti mbe loke Jordani Deut 3:25

1 mf A ro ibugbe Orun,
Li eba odo ti mole,
Nibit’ awon mimo wa laiku
Ti a wo won li aso funfun.
Lok’ orun lok’ orun )2ce
A ro ti ibugbe Orun

2 mf A ro t’ awon ore nibe.


Awon ti o ti lo saju wa.
Ati awon orin ti won nko.
N’il;e won ni afimn Olorun
Lok’ orun lok’ orun)2ce
A ro t’awon ore nibe.

3 Olugbala mi wa nibe.
N’be l’awon ibatan mi nsimi,
Je ki nfi ‘banuje s’apakan.
Ki nsi fos’ile abukun.
Lok’ orun ‘lok’orun.
Olugbala mi wa.nibe

4 mf Mo fere de ibugbe na.


Nitori mo r’ opin ajo mi,
Opo l’awon ti okan mi nfe,
Won ns’ ona won si duro demi.
Lok’ orun lok’ orun 2ce
Mo fere de ibugbe na)
Amin
971
8.6.8.6.7.7.6.
Nitori Odo-Agutan ti mbe larin ite.na ni yio si ma se amona won si ibi orisun omi
iye,Ifi7:17

1 mf Ao pade ‘oke odo,


Nigbose , nigbose ,
Okunkun y’o si rekoja
Nigbose , nigbose,
cr Gbati ajo ba pari,
Ao si ma ran bi orun.
Nigbose , nigbose,

2 f A o ma lu harpu ogo
Nigbose , nigbose,
A o ma korin irapada,
Nigbose, nigbose,
` cr Titi lae li orin na
Y’o ma f’ adun ro yi ka
Ebute ayeraye,
Nigbose, nigbose,

3 f Awa y’o si dabi Jjesu,


Nigbose, nigbose
Ti y’o fun wa l’ader iye.
Nigbose , nigbose
cr Awon angeli pelu
Ti nmu gbogbo ‘fe Re se,
Won y’o ma se ike wa.
Nigbose , nigbise.

4 f Omije oju wa, yt’o gbe,


Nigbose , nigbose ,
Pelu ayo nla ao si mo,
Nigbose, nigbose.
di Awon mimo t;o saju.
Lo si ile ayo na.
Pel’ ayo lao tun dapo.
Nigbose , nigbose.
Amin
972
6.6.6.6.8.8
Okan mi nfa nitoto fun agabala Oluwa.OD.84:2

1 mf Oluwa wa Orun
Ago Rel’aye yi.
Ibugbe ife Re.
Ewa Re ti po to.
ff Okan mi nfa s’ ibugbe Re.
O ns’ aferi Olorun mi.

2 mf Ayo b’awon ti nsun,


Nibit’ Olorun yan.
Tti nwon npara ibe.
Lati ma josin won.
ff Won nyin O sa, a yo b’awon
T’o fe ona oke Sion

3 f Lati ipa de’ pa


L’aye osi wa yi;
Titi won fi goke,
Ti won si yo s’orun.
ff Bugbe ogo ‘gbat’ Olorun
Ba m’ese wa de ibe na.

4 mf Olorun l’asa wa.


Imole at’ odi.
Owo re kun f’ebun
A ngba ‘bukun nibe.
ff Oun y’o f’ebun ore-ofe
Ati ogo fun iran wa.
Amin
973
10.10.10.10.
Iisimi kan ku fun awon eniyan Olorun.Heb.4:9

1 mf Kini ‘simi ayo; ailopin ni.


T’awon angeli at’ awon mimo ni.
mp Simi f’alare, f’awon asegun,
f Nibe l’Olorun je ohun gbogbo.

2 mf Tal’ Oba na, tani yi ‘te Re ka.


p Irora itura Re ha ti ri?
mf So fun ni, eyin ti njosin nibe.
B’ahon le titobi ayo na/

3 Jerusalem toto ilu mimo.


T’alafia re j’ayo ailopin.
Ar’ ohun t’a nfen’nu re, ka to.
A si rigba ju eyit’ a nfe lo,

4 L’agabara Oba wa, wahala tan,


Laiberu l’a o ma korin Sion;
Oluwa ; niwaju Re l’ao ma fi.
Idahun ‘fe han f’ebun ife Re.

5 cr Simi ko le tele, simi nibe


Enikan ni simi ti nw’ oju re.
f Nibe , orin Jubeli ko le tan;
mp T’awon mimo at’ angeli y’o ko.

6 cr L’aye yi, pelu’ gbagbo at’ adua


L’ao ma s’aferi le Baba orun.
f Bi igbekun ti nti Babiloni
mf pada lo si ilu Jerusalem.

7 p Nidsiyi, a wole niwaju Re.


cr Ti Eni ti ohun gbogbo ise.
mf Ninu eni ti Baba at’ Omo
Ati Emi je okansoso.
Amin
974
7.7.6 & Ref
Aa gbo kan ati Olusoagutan kan ni yoo si je.Jn. 10:16

1 mf Nihin l’awa nje ‘rora


Nihin ni a ma pinya,
mp L’orun ko si ‘pinya
f A bi o ti dun to,
Dun to, dun to, dun to,
A bi o ti dun to.

2 mf Awon t’o feran Jesu.


Won o lo s’oke orun
Lo b’awon t’o ti lo,

3 mf Omode y’o wa nibe


T’o wa Oolorun l’aye
Nigbogbo le eko,

4 mf Oluko , baba iya,


Won o pade nibe na,
Won ki o pinya mo,

5 ff Bi a o ti po to,
Gbat’ a ba r’ Olugabala
Ni ori ite Re.

6 Nibe l’ao korin ayo.


Titi aye ailopin ,
L’a o ma yin Jesu.
Amin
975
8.7.8.7.& Ref
Odo omi iye mimo, o mo gara bi Kristali Ifi.22:1

1 mf Ao pade l’eti odo


T’ese angeli ti te.
Tt’o mo gara bi Kristali
L’eba ite Olorun.
f A o pade l’eti odo
Odo didan; odo didan na.
Pel’awon mimo l’eba odo
T’o nsan l’eba ite ni.

2 mf L’eti bebe odo na yi


Pel’Olus’aguntan
A o ma ma rin a o ma sin
B’a ti ntele ‘pase Re

3 cr Nje l’eba odo tutu na,


A o r’oju Olugbala;
Emi wa ki o pinya mo;
Yio korin ogo Re.

4 p K’a to de odo didan na,


A o s’eru wa kale.
cr Jesu y’o gba eru ese;
Awon ti O de l’ade

5 A fe de odo didan na,


‘Rin ajo wa fere pin;
Okan wa kun f’orin
Ayo at’ Alafia.
Amin
976
8.7.8.7.8.7.
Jerusalemu mimo, ti nti orun sokale lati odo Olorun wa.Ifi.21:10.

1 f Salem t’orun ilu ‘bukun


T’o kun ‘fe at’ ayo
Ti a f’ okuta aye lo,
Ni orun giga loke;
Pel’ ogun angeli yika.
Tt’o nsokale b’iyawo.

2 Lat’ ode orun lohun wa.


L’o ti wo aso ogo
T’o ye Eni ti o fe o,
A o sin o f’ oko re.
Gbogbo ita, at’ odi Rre.
Je kiki oso wura.

3 Ilekun re dan fun pearl,


Won wa ni sisi titi,
Awon oloto now’ nu re
Nnip’ eje Olugbala ,
Awon t’o farada ‘ponju
‘tori oruko Jesu.

4 Wahala at’ iponju nla.


Le s’okuta re l’ewa;
Jesu papa l’Eni to won.
Si ipo ti o dara
Ife inu Re sa ni pe.
K’a le s’afin Rre l’oso,

5 ff Ogo at’ ola fun Baba


Ogo at’ ola fun f’Omo,
Ogo at’ ola fun Emi.
Metalokan titi lae.
At’ ayeraye okan na,
Bakan na titi aye.
Amin

977
8.7.8.7.7.7
Awon Ologbon yio yi b’irawo bi imole ofurufu. Dan. 12:3

1 f Tal’ awon wonyi b’irawo


Niwaju ite mimo,
Ti won si de ade wura,
Egbe ogo wo l’eyi?
ff Gbo won nko Aleluya;
Orin iyin Oba won

2 mf Tali awon ti nko inana


T’a wo l’aso ododo?
Awon ti aso funfun won
Yio ma funfun laelae,
Beni ki y’o gbo laelae,
Nibo l’egbe yi ti wa,

3 p Awon wonyi l’o ti jagun


F’ola Olugbala won.
Won jijakadi tit’iku
Won ki b’elese k’egbe
cr Wonyi ni ko sa f’ogun,
f Won segun nipa kristi,

4 p Wonyi lokan won ti gbogbe


Ninu ‘danwo kikoro
Wonyi li o ti f’ adura
Mu Olorun gbo ti won;
cr Nisisiyi won segun ;
Olorun re won l’ekun.

5 mf Awon wonyi l’o ti sora,


Ti won f’ife won fun krist’
Won si y’ara won si mimo
Lati sin nigbagbogbo;
Nisisiyi li orun.
Won wa l’ayo l’odo Re.
Amin

978
C.M
Idile kan li orun ati li aiye Efe. 3:15

1 f W a, k’a da m’ awon ore wa.


Ti won ti jere na,
Nn’ife k’a f’okan ba won lo.
S’ode orun l’ohun.

2 K’awon t’ aye n’nu Krist’ ni wa.


T’awon t’o lo s’ ogo,
Awa l’aye , awon l’orun
Okan ni gbogbo wa.

3 mp Idile kan t’ Olorun


Ijo kamn l’a si je.
di Isan omi kan l’oya wa.
p Isan omi now lowo,

4 f Egbe ogun kan t; Olorun.


Ase Re l’a si nse;
mp Apakan ti now lowo

5 cr Emi wa fere dapo na,


Y’o gb’ ade bi ti won,
f Ao yo s’ami Balogun wa.
Lati gbo ipe Re.

6 cr Jesu , so wa, s’amona wa.


‘Gbat’ oniko ba de.
f Oluwa pin omi meji,
Mu wa gunle l’ayo,
Amin
979
8.7.8.7.
Oluwa mo awon ti ise Tire ll:Ttim 2:19

1 mf Oba awon eni mimo


T’o mo ‘ye awon ‘ranwo;
Opo eni t’eda gbagbe
Wa yika ite Re lae.

2 mf Mole ti kuku aye bo


Ntan mole roro l’oke
Won je om-alade l’Orun
Eda gbagbe won l’aye.

3 mf Lala at’ iya won fun Oo,


Eda ko r’ oyin re mo;
Iwa rere won f’ara sin,
Oluwa nikan l’O mo,

4 di Won f’ara isura Re l’ ohun.


Ka wa mo won , Oluwa,
Nigbat’ o ba nsiro oso,
Ti mbe l’ara ade Re.
Amin
980
11.10.11.10.9.11.
Angeli Oluwa wipe , lo so gbogbo oro ipe yi.Ise A 5:20

1 mf Gbo, okan mi, bi angeli ti nkorin


Yika orun ati aye;
E gbo bi oro orin won ti dun to.
Ti nso, gbati ese ki o si mo,
p Angeli Jesu , angel’ mole,
Won nkorin ayo pade ero l’ona.

2 f B’a si ti nlo, be l’a si ngbo orin won;


p Wa, alare , Jesu l’o ni k’e wa;
cr L’okunkun ni a ngbo orin didun won.
mp Ohun orin won ni f’ ona han wa.

3 p Ohun Jesu ni a ngbo l’ona rere


Ohun na ndun b’agogo y’aye ka.
cr Egbegberun awon t’o ni si mbo,
Mu won w’ odo Re, Olugbala wa.

4 mf Isimi de, bi wahala tile po,


Ile y’o mo l’eyin okun aye.
cr Irin ajo pari f’awon alare
Won o d’orun ‘bi simi nkeyin .

5 f Ma korin nso, eyin angeli rere.


E ma korin didun k’a ba ma gbo,
cr Tit’ ao fi nu omije oju wa nu.
Tti a o si ma yo titi laelae.
Amin
981
7.7.7.D
E wo iru ife ti Baba fi ife wa, ti a fi npe wa ni Omo Olorun.Ijjn.3:1

1 f Alabukunn’nu Jesu,
Ni awon om’Olorun
Ti a fi eje Re ra.
p Lat’ inu iku s’iye ;
cr Ope , a ka wa mo won,
L’aye yi, l’orun.

2 f K’a to de ni Baba
Fe won ninu Omo Rre.
Nipa ‘gbagbo n’nu Jesu.
Ni won gba edidi yi,

3 f Awon ti a da l’are
Nipa ore ofe Rre.
A we gbogbo ese won,
Won o bo l’ojo ‘dajo,

4 mp Won ns’ eso ore ofe


Ninu ise ododo ,
Irira l’ese si won ,
Or’ Olorun ngbe ‘nu won,

5 Nipa ej’ Odagutan ,


Won mba Olorun k’egbe ,
Pelu olanla Jesu,
A wo won l’aso ogo.
Amin
982
D.CM.
Gbogbo awon angeli si duro yi ite na.Ifi.7:11

1 f Baba, niwaju ite Re.


L’angeli nteriba ;
Ni won korin iyin.
di Won si nfi ade wura won
Lele yi ‘te na ka.
cr Won nfi ohun pelu duru
Korin si Oluwa.

2 mf Didan osunmare si ntan


Si ara iye won’
ctr Serafu nke si Serafu
Ti won nkorin ‘yin Re.
p Bi a ti kunle nihinyi ,
Ran ore Re si wa.
K’a mo pe ‘wo wa nitosi
Lati da wa lohun.

3 f Nihin , nibit’ awon angel’


Nwo wa b’ a ti nsin O,
cr K’a ba won ile Orun.
K’ a sin O bi ti won ;
f K’a ba won ko orin iyin,
Titi agbara y’o fi di
Tire, Tire nikan.
Amin
983
C.M
Mo si gbo ohun awon angeli pupo yi ite na ka.Ifi.5:11

1 f E wa k’a da orin wa po.


Mo t’ awon angeli;
Egbegberun ni ohun won.
Okan ni ayo won.

2 Won nkorin, pe, Ola nla ye.


Od’agutan t’a pa;
K’a gberin pe Ola nla ye.
p N’tori O ku fun wa.

3 mf Jesu li o ye lati gba.


Ola at’ agbara ;
cr K’iyin t’enu wa ko le gba
Je Ttire, Oluwa..

4 f K’awon t’o wa l’oke orun


At’ ile at’ okun
Dapo lat’ gb’ ogo Re orun
Jumo yin ola Re..

5 ff Ki gbogbo eda d’ohun po,


Lati yin oruko
Eni t’O joko l’or’ ite,
Ki won si wole fun.,
Amin
984
7.7.7.6.
Kristi feran ijo Re o si fi ara Re fun u,Efe5:25

1 mf Jesu , ba ijo Re gbe


S’amona at’ odi re.
B’o ti nla ‘danwo koj’
Awa mbe O, gbo wa.

2 mf F’owo ife Rre yi ka.


Dabobo lowo ota,
Tu ninu nigba ibi.
p Awa mbe O gbo wa.

3 mf M’eko at’ iwa re mo,


Je k’ofi suru duro;
K’o simi le leri’ Re
Awa mbe , O gbo wa.

4 mf Pelu rel’ojo gbogbo ,


K’o bo lowo sina,
K’o ma sise fun ‘yin Re.
Awa mbe O, gbo wa.

5 cr K’ohun re ma ja goro
Ni’ikiko ‘dajo ti mbo;
Nisiso ife Jesu,
p Awa mbe O, gbo wa.

6 mf Wa tun ibaje re se,


Wa tun Tempili Re ko,
Fi ara Re han nibe,
p Awa mbe O, gbo wa.

7 cr Wa da gbogbo ide re.,


Mu ‘lara at’ ija tan.
M’alafia orun wa.
p Awa mbe O, gbo wa.

8 mf Mmu gbogbo ona re to


Ma jek’ owo esu te
Ki aye ma tan je.

9 cr K’eko re je okan na.


N’nu otito at’ ife;
K’o fa opo si gbagbo,
p Awa mbe O, gbo wa.

10 mf K’o ma toju alaini


K’o si ma wa asako
At’ onirobanuje ;
Awa mbe O,gbo wa.

11 mf Ma je k’ife re tutu,
N’awon oluso gboya,
S’agbara y’agbo Re ka.
Awa mbe O,gbo wa.

12 mf L’awon alufa ma bo,


Ki won j’oluso toto.
Lati ma to ijo Re.
p Awa mbe O,gbo wa.

13 mf Ki won se bi won ti nso,


K’won f’apere mimo han.
Bbi asaju agbo Re.
p Awa mbe O,gbo wa.

14 F’or’ofe eni t’o ku,


At’ ife Baba ba gbe.
K’Emi ma s’amona re.
p Awa mbe O,gbo wa.

15 mf We gbogbo arun re nu,


L’eru on ‘yemeji lo,
Mu ‘segun Re de kankan,
Awa mbe O,gbo wa.

16 p Ran ‘lowo nigba awe


cr Tit’ ise re o pari;
f T’oko yawo y’o si de
p Awa mbe Oo,gbo wa
17 ff Nigbana k’ ose logo
Ninu aye t’Iwo npese;
K’o n’ibukun nibe lae.
p Awa mbe O,gbo wa.
Amin

985
8.8.8.6.5 Ref.
Won nfe ilu kan ti o dara jube lo,Heb 11:16

1 cr L’ojo kan sa, ti nko le so,


Un o dagbere fun ‘banuje
Un o ba awon angeli gbe,
Ojo, ojo ayo.
mf Ojo ayo(2)
T’emi y’o ma ba Jesu gbe.
Ojo,ojo ayo.

2 mf L’ojo kan ‘nu bode didan,


Emi y’o gbe harpu wura;
Un o wo aso funfun laulau,
Ojo,ojo ayo.

3 L’ojo kan un o r’ Olugbala ,


On yio si gba mio mora
Y’o si ka mi kun ayanfe
Ojo,ojo ayo.

4 mf L’ojo,kan sa emi mo pe
Un o ri awon t’o ti koja.
Un o mo bi ‘gbesemi ti to
Ojo,ojo ayo.
Amin
986
8.7.8.7.8.7.8.7.& Ref
Nnigbati Oo ba farahan, a o dabi Re.1Jn.3:2

1 cr ‘Gbat’ ikuku ba rekoja


T’ojo titun ba de ;
mf Ti tanasan orun farahan
L’or’ awon isan omi.
Tt’a nranti leri Baba wa.
N’nu didan osumare ;
A o ra wa ju t’ isiyi
Gbat’ kuku ba koja
f L’owuro jo didan ni.
Ojo t’o logo julo
A o mo ra wa ju t’isiyi
Lae ka da nikan rin.

2 mp Nisisiyi , a rin ajo wa.


N’nu aro on isoro;
p Nisiyi , a nse wa nise.
Nihin at’ ibi gbogbo;
cr Sugbon ao gb’ ohun Baba wa.
Pe, ‘E wa eyin Oomo,
L’owuro ojo didan ni,
Gbat’ ikuku ba koja,

3 f Gbana okan wa y’o f’ayo


Yi ite ogo Re ka.
A o ri awon t’o fe wa.
A o mo b’a ti mo wa.
Orin rapada wa l’ao ko
Ttiti lae ati laelae.
‘Gbat’ isudede ba kuro
Tt’ikuku si rekoja.
Amin
987
7.6.7.6.D
Mo si ri ilu mimo ni, Jjerusalemu titun , ilu na si je kiki wura Ifi 21:2, 18

1 mf Jerusalemu ilu na.


Ti wara , oyin nsan
Itunu ni fun okan
Ti nronu nipa re.
f Tani le so ayo nla
Ti nduro de awa
Ilu ogo titi,

2 Won duro loke Sion ,


ff Won nkorin ayo nla ,
Gbogb’ awon ajeriku
At’ awon angeli,
Oluwa mbe larin won;
Ojo tu won lara.
Ilu awon ayanfe,
Ilu ogo julo.

3 Omo Dafidi njoba


ff Ko si aniyan mo,
Iho ayo isegun;
Orin irapada
Awon asegun won pelu
Balogun won dapo
Won wo aso isegun
Titi ayeraye.

4 Ilu alabukun fun.


Ile ayanfe Re ;
Ilu opo ibukun
F’okan ti npongbe re.
Jesu , jewo se wa ye,
Nibiti Iwo , Baba
Ati Emi gbe wa.
Amin
988
7.6.7.6.D
Iwo si ti fi eje Re se irapada eniyan si Olorun lati inu eya gbogbo ,Ifi.5:19

1 mf E gbegberun aimoye,
Won wo aso ala;
Ogun awon t’a rapada
Won kun ‘bi mole na,
f Ija won pelu ese
At’ ilekun wura sile.
Fun awon asegun .

2 ff Iro Aleluya won.


Lo gb’aye orun kan.
Iro egbegberun harpu
Ndaun pe segun de tan.;
Ojo t’a s’eda aye.
T’a da orile ede,
Ayo nla pa ‘banuje re
Ti a fun ni kikun.

3 f A ayo t’a ko le so;


Leti bebe kenan;
Idapo nla wo lo to yi.
Ibi t’a ki npinya;
Oju to kun fekun ri.
Y’o tan mole ayo,
Ki y’o si alaini baba,
Opo ki y’o si mo.

4 Mu ‘gbala nla Re fun wa,


Od-agutan t’apa,
Ko ruko awon ayanfe,
Mu ‘pa Rre k’o joba ;
Wa ife orile ede.
Da onde Re sile,
Wa fi ami leri Re han,
Wa, Olugbala wa.
Am

989
7.7.7.7.D
Awon wonyi li o jade lati inu iponju nla,Ifil.7:14

1 mf Tal’ awon yi t;aso won


Nndan ju orun osan lo,
Asju omo mole,
T’o sunmo te,Olorun?
Awon yi l’o ti jiya,
Nitori Oluwa won,
Ati ninu isin Re.
Won l’o to Kristi leyin.

2 mp Won t’’iponju wa,


Won f’eje Od-agutan
Fo’ so won nipa ‘gbagbo
Eje na ti we ni mo;
cr Nitorina won njosin
Leba ite Eleda;
Olorun si mba won gbe
Inu Re si yo si won.

3 mf Won ta’ won asegun yo;


Idanwo won ti pari;
Gbogbo ise won koja
Ebi, onigbe, ko si mo;
Oru ko mu won n’tori
Owo orun ko de ‘be,
Ilu tura ni won ngbe ,
Ibi ‘mole ailopin .

4 Od-agutan l’ori te,


Y’o ma bo won n’gbagbogbo ,
Y’o f’ onje iye bo won,
Y’o f’omi ye fun won mu.,
Gbogbo aini won y’o tan
Y’o nu omije won nu,
Y’o f’ ife kun okan won.
Amin
990
C.M
Won si segun re nipa eje Odo-agutan na ati nitori oro won.Ifi.12:11

1 mf Mba le f’iye igbagbo fo,


Wo inu ikele;
Ki nri ayo awon mimo,
B’ogo won ti po to,

2 cr Mo bi won bi won se segun;


Won f’ ohun kan wipe,
Agbara , Od’agutan ni,
Iku Re, l’ayo won.

3 Won kiyesi ipase Re.


`Itara Re mu won,
Nipa gbigbo t’ Oluwa won
Won jogun isimi,

4 f O to k’a yin Amona wa,


F’apere t’o fun wa,
Bi opo awon eleri
Tti nf’ ona orun han.
Amin
991
8.8.8.D
Nwon simi kuro ninu lala won,Ifi.14:13

1 mf Awon mimo,lala pari


Won ti ja, won si ti segun
Won ko fe ohun ija mo
Won da won ‘le l’ese Jesu
cr A eyin eni ibukun
p Isimi yin ti daju to,

2 mf Awon mimo , irin pari.


Won ko tun sure ije mo,
Are at’ isubu d’opin
Ota on eru ko ri mo
cr A eyin eni ibukun
p Isimi yin ha ti dun to,

3 mf Awon mimo , ajo pari,


Won ti gun sile ibukun
Iji ko d’ eru ba won mo,
Igbi omi ko nipa mo,
cr Sa eyin eni ibukun
p E nsimi n’ibi alafia ,

4 Awon mimo,oku won sun


Ninu ile,awon nsona
cr Titi won yoo fi jinde
Lati fi ayo goke lo,
f A eni ‘bukun , e korin
Oluwa at’ Oba yin mbo,

5 mf Olorun won,wo l’anke pe,


Jesu ,bebe fun wa l’oke
Emi Mimo, Oluto wa.
p F’ore-ofe fun wa d’opin
cr K’a le b’awon mimo simi
Ni paradise pelu Rre.
Amin
ONIRUURU.

1
12.12.10.11.10.4.
Ki Olorun ki O sanu fun wa, Ki O si busi fun wa. OD.67:1

1 f Bukun’le wa at’ebi wa, at’ara wa-2ce


Ibukun orun, irawo re,
mf Ibukun orun ko fi kari awa,
K’O fi fun wa o, l’aye l’orun,
Baba Orun.

2 f Tu wa lara, Alagbara, se ‘toju wa,-2ce


Itunu Re, alafia Re,
mf Ike Re, k’O fi toju wa, ye,
Awa mbe O o, gbo adura wa,
Oba ogo.

3 f Baba fun wa l’Emi mimo at’agbara -2ce


Iranse orun, ebun lat’orun
mp Itunu Baba, k’o wonu okan wa,
K’o gbe ‘nu wa o, k’o fun wa l’ayo,
Oba Orun.

4 mf Awa f’iyin at’ope fun Baba l’orun -2ce


Iyin fun ‘ranwo, ope fun anu,
f Ayo fun ‘dasi ti a ri lojojo.
Ope fun O o.a tun juba Re,
Baba awa. Amin.
2
13.9.8.8.10.6.
Gbo ohun ebe mi, nigbati mo ba nkigbe pe O. OD.26:2

1 mf Emi y’o gbadura s’Oba mi, Edumare,


Baba, ye ko wa gba mi o e,
f Okansoso Ajanaku,
Wa pelu mi, ye Baba o;
cr Emi, omo Re,nkepe O o,
Baba, waa duro gbo.
2 mf Emi y’o gbadura ss’Oba mi, Edumare,
Baba , ma fi mi sile o e;
f Baba mi lowo olubukun;
Wa sile mi nile Re o.

3. mf Emi y’o gbaadura s’ Oba mi, Baba rere,


Ma jeki’ emi padanu o e,
f Iwo ni Oba aiku ,
Wa pade ini n’ ile Re o.

4. mf Emi y’ o gbadura s’ Oba mi, Edumare.


Baba, wa fun mi l’ ere o e
f Okansoso Ajanaku,
Ye bukun mi n’ ile Re o.
Amin.
3.
9.9.9.9& Ref.
Emi o ma yo ninu Oolorun igbala mi.

1`. f Okan mi yin Oluwa logo,


Oba iyanu t’ O wa mi ri,
Un o l’agogo iyin y’ aya ka,
Un o si f ife Atobiju han.,
f Oluwa, ope ni fun O
Fun ore-ofe t’ Ofi yan mi;
Jowo dimimu titin dopin
` Ki nle joba pelu Re loke.

2 m Bi eranko l’emi ba segbe


cr Bikose ti Oyigiyigi;
Lairotele l’Emi Mimo de
f T’o f’ede titun si mi l’enu.

3 f Ayo okan mi ko se rohin


Loro, losan, loganjo oru;
Gbat’Emi Mimo ti de ‘nu mi
Mo nkorin orun lojojumo.

4 mf Jesu ti la mi loju emi,


Mo si f’eti gbohun ijinle;
f O nse faji ninu okan mi;
mp Kini nba fi fun Olugbala?.

5 f Em’o sogo ninu Oluwaa


K’emi ma baa di alaimore;
B’o ti pe mi iyanu l’o je;
Awon angeli d’olufe mi.

6 mf Mo damure lati sin Jesu


Laaifotape larin aye yi;
Nibikibi t’o ba nto mi si
O daju ko ni jeki ndamu.

7 `mf Bi mba pari ‘r-ije l’aye,


Olugbala, ma je ki npofo;
Ni wakati na jeki ngbo pe
Bo sinu ayo ayeraye. Amin.
4
Adura ki adura tabi ebe ki ebe ti a ba ti odo
enikeni gba, ki Iwo ki o si san fun olukuluku
gegebi gbogbo ona re. 11kro.6:29 &30.

f Baba, awa yin o o,


Baba, awa yin O o,
Baba, awa f;irele josin fun O o,
Edumare.

1 Awa dupe pe O da wa si,


A ri owo ibukun Re ni aye waa sse,
mf Baba, awa f’irele josin fun O o .
\ Edumare.

2 f O seleri irorun ninu ohun gbogbo,


O pese ile ijosin ni akoko yi,
mf Baba, awa f’irele josin fun O o;
Edumare.

3 mf Aw’omo Re ti O misi o lati seyi fun O,


F’alafia at’emi gigun at’aye fun wa;
Baba, awa f’irele josin fun O o.
Edumare.

4 mf Aw’omo Re ti O sairi o lati seyi fun O,


F’ijoba orun sike wa o nikeyin aye wa;
Baba, awa f’irele josin fun O o
` ` Edumare.

5 mf Eyin ogun oorun, sokale, e ya ‘hin mimo,


E fi ibere wa fun waa l’akoko gbogbo;
Baba, awa f’irele josin fun O o.
Edumare.
Amin.
5
8.6.6.6.7.10.
E korin ssi Oluwa, fi ibukun fun
oruko Re, e ma fi igbala Re han
lati ojo de ojo.OD.96:2.

1 mf E fi ‘bukun fun Olorun,


Olodumare ni;
Eni t’O da aye,
At’ohun inu re,
Fun ike omo eniyan
Iyin, ola at’ogo f’Oluwaa!.

2 f Olubukun at’Ologbon,
‘Wo Ologo l’a yin;
Eni t’o da wa si,
To bukun ise wa,
To si ngbe ori wa ga,
Iyin, ola at’ogo f’Oluwa.

3 mp ‘Gbati ese wa fi wa sun,


p T’okan wa banuje,
cr Igbe wa ke t’o lo;
O si gbo ebe na;
O si da wa ni nde .
Iyin, ola at’ogo f’Oluwa!.

4 f Iyin lo ye kristi Obaa;


E de l’ade pupo;
Eni t’O fi ife,
‘Mole at’emi Re
Mu ‘rapada wa s’aye;
Iyin, ola at’ogo f’Oluwa!.

5 ff B’irun mi jek kiki ahon,


Ko to fun iyin Re;
B’Olorun tile ga
Ju gbogbo iyin lo,
Sibe un o korin ope;
Iyin, ola at’ogo f’Oluwa!.
Amin.
6
11.17.11.7.& Ref.
Awa feraan Re, nitori On li o ko
feran wa. 1Jn.4:19.

1 f Iwo to fe wa la o maa sin titi


Oluwa Olore waa;
Iwo to nso wa n’nu idanwo aye,
Mimo, logo ola Re.
mf Baba, Iwo l’a o ma sin,
Baba, Iwo l’a o ma bo,
Iwo to fe wa l’a o maa sin titi,
Mimo l’ogo olaa Re.

2 f Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’aye


T’aye fi nrohun je o;
Awon to mura lati ma s’oto,
Won tun nyo n’nu ise Re.

3 ff Iwo to nf’agan l’omo to npe ranse


Ninu ola Re to gaa;
Eni t’o ti s’alaileso si dupe
Fun ‘se ogo ola Re.

4 mf Eni t’ebi npa le ri ayo ninu


Agbara nla Re to ga,
Awon to ti nwoju Re fun anu .
Won tun nyo n’nu ise Re.

5 f F’alafia Re fun ijo Re l’aye


k’ore-ofe Re ma ga,
K’awon eni Tire lo ma yo titi
Ninu ogo ise Re. Amin.
7
10.10.10.10.12..16.16.10.
Nitori Oluwa po li ore; anu Re ko nipekun. OD.100:5.

1 mf E mi y’o san ore o f’Olorun mi)2x.


Eni da mi si o latesi wa )2x
Fun jije, fun mimu, t’o n b’asiri mi
Fun ipese lojojumo l’ona ara jaburata
Ko je k’aye yo mi, loju elegan aye mi dara
f Emi y’o f’ore han f’Olorun mi.

2 ` E jek’ a sajoyo f’ope oni)


Eni ba m’ore Re waa ka s’ope )2x
F’ori wa to dara, ti O bukun fun wa
O fi gbala da wa ola, O pese ohun gbogbo
Ko jek’ awa segbe, loju elegan, O gbe wa ro o
Eni ‘nu re ba dun je ko yo o.

3 f Emi y’o yin Jesu, Oba ogo)


Olu seun ara, O m’ayo mi kun )2x
O da mi lola o, o tun pe mi l’omo
O f’ohun atata le mi lowo, ohun ijinle to daju
Ko jek’eru ba mi, loju elegan o ye mi si o
Emi y’o yin Jesu, oba ogo.

4 E jek’a f’ope f’Olorun wa)


Eni da wa si o d’ojo oni )2x
O fun wa logbon o, O tun pe wa sagbo
Omo Igbala mura giri, ko ma foya rara rara
Duro ninu’gbagbo, lojo aye re, dara fun o
E jek’a f’ope han f’Olorun wa. Amin.
8
11.11.11.12.& Ref.
Oro na si di ara, on si mba wa gbe, (awa si nwo ogo re,
ogo bi ti omo bibi kansoso lati odo

Baba wa.) o kun fun ore-ofe ati otito. Jn.1:14.

f E ba wa yin Oluwa, Aleluya!


Eni ba more Jesu k’o ba wa gbega,
E ba waa yin Oluwa, Aleluya!
Eni ba more Jesu k’o ba wa gbega
Eni ba more Re k’o ba wa gbega
E ni more Re k’o ba wa gbega
E ba wa yin Oluwa Aleluya!
Eni ba more jesu k’o ba wa gbega.

1 mf E ni t’O f’orun sile t’O wa s’aye,


p Lati ku fun ese araye gbogbo;
cr E korin Aleluya s’Oba mimo
Eni ba more Jesu k’o ba wa gbega.

2 mf Eni t’O npa wa mo o, lojojumo,


Eni t’O nyo wa ninu ewu gbogbo,
Eni t’O npa Israeli mo k’itogbe;
f Eni ba more Jesu k’o ba wa gbega.

3 mf Eni t’O npese fun aini wa l’aye,


Eni t’O nsore fun wa l’ojo gbogbo,
cr Ore t’O nse fun wa ko l’onka rara;
Eni ba more Jesu k’o ba wa gbega.
Amin.
9
A bi Olugbala fun nyin loni ni
ilu Dafidi, ti ise Kristi Oluwa. Luk.2:11.

1 mf Iyin f’Eni Mimo,


Iyin f’olu agbaye,
Iyin fun Jehofa loke
T’O f’Omo iyan fun wa
cr Ipe ndun l’orun pe; a bi Oba wa,
f Ogun orun nkorin ogo,
Ogo ni fun Olorun,
E ku ayo Omo, gbogbo eniyan
A bi Jesu Oba.

2 mf Ogo f’Eni Mimo,


Eleda ohun gbogbo,
Ogo ni fun Olodumare
T’O ran Messiah w’aye;
Ipe ndun l’orun pe :”a bi Omo Oba”
Angeli nkorin pe
“Alafia fun eniyan:
E ba wa yo gbogbo eniyan
Olugbala wa wa s’aye.

3 Ise Oluwa iyanu ni


O gbe ‘nu Wundia sola,
O gb’ona iyanu mu ‘gbala w’aye
Eniyan sorire, eniyan sorire.
Elerunyin, O ma se o,
A bi oba iyanu)
Ipe ndun l’orun pe: “a bi Oluwa wa”.
Ogun orun nkorin ogo,
Ogo ni fun Olorun:
E ku aye Omo, gbogbo eniyan
A bi Jesu Oba. Amin.
10
15.6,15.6. & Ref.
Ijo eniyan nkigbe wipe, Hosanna fun Omo Dafidi!
Olubukun li eniti o mbo wa li oruko
Oluwa! Hosanna loke orun. Mt.21:9.

1. mf A won Omode s’eka wewe at’ imope s’ ona,


f Won si nke, Hosana,
Eyi ni orin ‘segun t’a ko wonu Jerusalem
ff Hosana ‘ Hosanna!
f Eyi l’omo nla Dafidi ati Oba Israeli!
O gun ketekete lo fun igbala omo eniyan,
ff Hosana! Hosana!
Hosana si Omo Dafidi!

2 mp Awon agbagba gbiyanju lati pa won lenu mo,


f Won tun nke Hosana;
mf B’awon wonyi pa enu won mo, okuta yo soro,
f Hosana! Hosana!

3 mf E so fun Omobinrin Sion pe Oba re mbo wa


f Hosana! Hosana!
cr O tenu, O si joko lori omo ketekete,
f Hosana! Hosana!

4 .f Oluubukun l’Eni ti mbo wa l’oruko Oluwa!


ff Hosana! Hoossana!
mf E te okan yin si ona fun kristi, Oba Ogo,
f Hosana! Hosana!Amin.
11
7.5.7.5.6.5.5.4
Sugbon enyin o gba agbara, nigbati
Emi mimo ba ba le yin Ise.A.1:8

1 mf Emi Baba Alaye,


Sokale pelu
Agbara pentikosti;
So okan waa ji,
f Ki O si mu gbona;
B’inaa orun, wa
Peluu ‘tunu nla:
Tan ‘mole re.

2 mp Aye ati emi wa,


Gba, fi se Tire;
Ninu isin wa fun Oo
Ka ni ‘ranwo Re
Lati j’olotito;
K’ebun at’orun
Ti pentikosti
Ba s’ori wa.

3 cr Fi eje ‘yebiye Re
T’oke Kalfari
We okan ese wa nu;
Si ra wa pada;
q Fi ‘fe kun aya wa,
Ka rin ‘na oto
Ife Re lao se
Bi ti orun.

4 mf Baba,Omo on Emi,
Metalokan lae,
f Iyin, ogo, agbara
JeTire nikan;
Ewa Re l’aye yi,
Yo je ayo wa
Pelu idupe,
Aleluya!. Amin.
12
11.9.11.9.& Ref.
Emi Oluwa Jehofa mbe lara mi Isa..61:1..

1 mf A ti mu mi l’aginju aye yi ja
Lori ooke ati petele;
Ko si ohun kan t’oo wu mi ninu re,
A fi Jerusalem t’orun.
f Ojo mbo t’a oo dagbere
Fun aye pe o digbose;
Ojo mbo, ara, ojo mbo
Ti a o lo s’ile wa loke.

2 mf Mo duroi, mo wo ena Jerusalem,


Okan mi npongbe lati dde’be;
Ohunkohun yti y’o ba mu ‘dna waa
Metalokan ba mi mu kuro.

3 mf Ojojumu l’okan ese mi npada


Kuro lodo Jesu Oluwa;
Jowo,Jesu, f’eje mimo Re ra mi,
F’Emi Mimo Re to mi sona.

4 mf Aye nti mi sihin, nwon nti sohun,


Se, nko ni pada lodo Jesu;
Mo seleri lati ba Jesu joba
Ileri na ko ni tase lae.

5 mf A ti fi ile rere Kenan’ han mi,


Ewa re ko se f’enu ro in
Ara, bawo l’eyin o ha se de ‘be?
Okan ti ko de ‘be padanu..

6 mf Eyin ara, e ba mi yin Oluwa


T’O f’ona Aposteli han mi;
L’ojo oni mo mo Jesu l’Oba mi
O f’Emi Mimo Rre kun ‘nu mi.

7 mf Jesu, jowo di mi mu titi d’opin,


Ki nle ba O d’opin l’oo dun ju;
f Aleluya! e yin Jesu l’ekan si,
Aleluya! l’orin ikehin!. Amin.

You might also like