Professional Documents
Culture Documents
Iwe Asiri Agbara Aditu Volii Complete.
Iwe Asiri Agbara Aditu Volii Complete.
EYONU
1- EYONU AWON AJE
Odindi okete tutu, ao ge gbogbo iru re ati ori re kuro. Ao tu ifun re
danu. Ao fo dada. Ao wa ge okete yen kekeke sinu awo sobi tio ba
di ale, ao fi eko kan le lori. Ao bu opolopo epo pupa le, eepo iginla
die, eepo obo die, orogbo kan, obi abata kan, atare kan. Ao ko le
lori. Ao gbe siwaju ita gbangba ile wa. A ki gbesi orita meta rara o.
Ako gbodo jade mo ti abati gbe sita. Bi ile ba ti mo, ao lo ko
gbogbo ohun ti o wa ninu awo yen yatosi orogbo ati obi pelu atare.
Ao wa fi ori okete yi tele inu ape. Ao fi okun ti oku si oju ona si ati 26
ewe kilefimise ati gbogbo ohun ti ako ninu awo ipese yi. Ao jo po.
Ao fi epo pupa si ori aro meteta. Ao wa jo ,at a ijosi ni ao ma fi ko
ina re , ti abati jotan ao tenu ejiogbe ao pe ohun re si
lilore: ni ale ao bu epo pupa sinu abo loto lona meji, ao bu etu yi si
ona mejeji ao fi iyo sinu ikan ao la iyen, ao fi eyiti ako fi iyo si yen
para ako gbodo jade movtiti ile yio fi mo.
Ohun Re : ise kii se aiye ku emi l omo. l ma se ise laiye mi edi ki di ile
kin ma sise laiye mi ki edi ma my mi, ebo riru kii mu ogun , odifa
fun alafia nigbati onti ikole orun bo wa si ikole aiye, nigbati ode ile
aiye , osho ile ni awon yio gba nkan tie lowo re, oni sebi moti rubo
fun esu, won kini ofi rubo, oni ewureewure ewure, woni awon kofe
oni obuko, woni awon kofe, oni ikeregbe dudu toun ti omo redede
labe, woni awon kofe, oni emi ( kini) eo gba, nigbati ogbe okete
de. ode oya enu koto orin awo bo silenu, onse iya gba okete gba
okete, iya osoronga, iya gbokete ma gba eniyan, iya osoronga, owo
ti mo ni ti yin ni,aso ti mo ni ti yin, kin di eniti gbogbo aiye yoo ma
mo si rere lati oni lo, adura.
2- EYONU :
Epo die 2. iyo die 3. omi die ao ro po, ao te ifa eji ogbe si pelu ofo
yii. omo pon loruko ti a npe epo 3x omo dun loruko ti a npe iyo 3x
awaye ma te loruko ti a npe omi 3x omo pon loruko ti a npe epo, ti
lagbaja ba je epo loni ki o ma yonu si emi lagbaja 3x omo dun
loruko ti a npe iyo, ti lagbaja ba je iyo loni ki o ma yonu si emi
lagbaja 3x awaye ma tee loruko ti a npe omi, ti lagbaja ba mu omi
loni ti o ba ti ri emi lagbaja ki o ma yo mo emi lagbaja loni yi o ao
la epo yen ao fi iyoku paa oju
3- EYONU (Eleyi ni ogun ti won koki finji eyan gbe tabi eni basi
oko wo)
ao jo odidi asin gbigbe tabi tutu pelu odidi atare kan aofi sin
gberen meta si orike rike arawa tiaba wo motto awon soka wonma
ja yan bole bi asin senrun niao marun ni asiko yen osele simi emi
ati olori agba ati omo tuntun lowo uturn leko lati wo mottoye
27
esekese lati bole
8- EYONU
Ewe akoko ati itanna re, epo ati egbo re ao jo pelu odindi ataare
kan, ao maa fi epo la ki a to sun... ti o baa di ojo keje ti a lo ise yii
ao fi akara elepo se sara fun enia meta pere odaju
13- EYONU
Ewe ejinrin, ao su losuka ni ona meta, ao gbe eyokan le inu ape
ejo ogun, ao ki eyin ororo kan bo larin ao ko ewe anu bo mole,
ao gbe ekeji le lori ao fi eyin ororo kan si ao tun ko ewe anu bo
loro, be lao se to titi de ori eleketa, ao waa paa epo obo ati igi nla 30
le lori pelu odindi ataare kan, ao jo papo ao gbodo ro raaraa titi
yio fi jo tan, ao lo kuna daadaa ao pin si ona meta, ao fi idakan
po ose dudu, ao fi idakan foko tutu mun ao daa idaketa sinu oyin
gidi...
Lilore : Ti ose yen ojo meta meta ni ao maa fi we ki a to sun ni ale,
edakun ati isale ni ao ti maa we lo soke ooo. ao gbodo we lati
oke waa si isale ooooooooo, iwo ti o baa waa ni ipo giga kan bi
o baa file we ose yii lati oke wa si isale ha!!!!!!! olohun koni so
waa di eni ile ooo, oke loke ni ao maa lo, ao ni waa le lailai....
eyiti ao fi foko mun, owo alafia ni ao fi fo, owo alafia ni ao fi
gbemun, ori oke to baa gaa ni ao ti lo gbemun, bi o baa wuwa ki
a gun ori ope lo, ese waa ko gbodo kan ile raaraa, eyiti ao maa fi
oyin laa, ika owo ti o gaa ju ni ao maa fi laa ni araro ki a to soro
si enia..... kunfayakun ti olohun allah ni....
14- EYONU
Eyin ibile 4 ewe omisinmisin gogoro ewe omisinmisin olokun
iyere epo iyo kekere isasun tuntun ao bo eyin yen ao bo epo re
kuro, ao wa lo gbogbo eroja yoku po ao fi se eyin yije, ao je
pelu adura. haa! gbogbo nkan ti olorun da ni yio ma yonu si e,
titi de ori oso ati aje ati gbogbo omo eda eniyan patapata. koda
alijan-nu yio yonu.
25- EYONU
Ao wa ewe ajaobale, ewe egele, ewe boboawodi, epo igi nla,
epo obo, isu gudu gudu, eyin adie ibile kan, ao gun papo mo
ose, ao ko sinu ike fufun kan, ao mofi we ni araro. Odaju
33- EYONU
Eru oju arọ, enpo ọbọ ao lọ kuna daadaa ao mo mo ọse lux ao
maa fi we lalale. odaju
41- EYONU....
Egbo tude, ata ijosin meji, eyo atare meji, lilopo, ao fi sin gbere
yika orun owo wa mejeji.
42- Eyonu
Eye oge kan, oga gbigbe kan, ewe ewuro, odidin atare kan jijo
po ao mafi foko mu.
45- EYONU
Egbo tude ata ijosin meji eyo atare meji lilopo ao fi sin gbere
yika orun owo wa mejeji.
46- EYONU
Eye oge kan, oga gbigbe kan, ewe ewuro, odidin atare kan jijo
po ao mafi foko mu.
ASINA
72- ASINA
Adan 1, oobe 1, obi ajopa 1, atare odidi 1, ajopo ama fifo eko
mu lago kan oru, ama fi eyin tilekun ti aba nfo lowo ti a fi mu
tan. ofore:~ agbasi agba ti, bi oso batilekun aje ni nsi, bi aje ati
oso batilekun emere ni nsi, bi oso,aje ati emere batile
eledumare ni nsi,ki ilekun ola,owo,omo,ifokanbale, igbega. ,
ki o wa si funmi.awamu.
75- ASINA
ao han bisimilahi 12,000 ao fi omi ti eiyele mun ku fo ao jo
awo lili ti won bo pelu ori re, obi ati orogbo kan, odindi ataare
kan, ao jo ao fi mun hantu yii ni igba ti o ba wuwa.. obi abata
ni o
78- ASINA
Ao han bisimilahi 12,000 ao fi omi ti eiyele mun ku fo ao jo
awo lili ti won bo pelu ori re, obi ati orogbo kan, odindi ataare
kan, ao jo ao fi mun hantu yii ni igba ti o ba wuwa.. obi abata
ni o
OSHOLE
98- OSOLE (ITAN NA ASIDE TI A NFI PE OWO)
Ewe sawerepepe, Ewe Ewuro, Alagemo gbigbe kan. Ao lo
awon ewe yen po. ao le mo ara Alagemo yen. ao ju sinu igba
pelu odindi ataare kan. ao jo po.. Ao lo kunna daadaa, ao da
sinu Fitila oloju 16, ao da epo pupa si pelu owu akase... Ao tan
ina si ni dede agogo kan oru pelu ofo yii.. Olulana 3 times
Lana rere ko mi 3 times Ewe Ewuro loni ki eyin Omo Araye
mun temi Lagbaja omo Lagbaja ro ni rere 3 times Sawerepepe
sare tete ki olo pe owo temi wa loni 3 times Abati Alagemo 53
bada ni orisa oke ngba 3 times ao ma sa adura bi o ba ti
wuwa... Ao maa tan ina si fun 16 days ni ago kan oru ni ao ma
saa Odaju
107- OSOLE
Odindi Okete kan ao gbe tele ape ao ko eyin Oror mefa ti
legbe pelu odindi ataare mefa ao jo pelu opolopo ewe ajeobale
lelori ao lo kuna daadaa epo pupa tabi oti schnapp ni ao maa fi
lo lalale.
112- OSOLE
113- OSOLE TO DAJU
Eye elulu kan, ori okete kan, ewe abamoda niwonba, ewe aje
tutu niwonba, odidi atare kan, ao jo po, ao fi milk olope kan lo
lago Mejila oru ojo alamisi. Yo mu odidi eyan to yanju wa, ti a
ba fe ma lo diedie, ago mejila alamisi na ni yo ma je pelu milk
na, sugbon ise ashina ni yo se o.
127- OSOLE
Odidi musu kan, ewe orijin topo die, odidi atare kan, ao du
musu yen sinu agbada, ao la musu yen ni inu, ao fi atare bo inu
re, ao ko ewe yen sinu e, ao da iru woro naa sinu e, ao ko ewe
orijin le, ao wa jo. Ao ma lo pelu omi aye lararo tabi lalale.
62
128- OSHO OWO..
Akara elepo eyokan, ao lu lori, ao ki eran ajiyo die bo. Ao lu
legbe otun, ao ki afomo abe obinrin bo. Ao lu legbe osi, ao ki
atare ajabo, ao wa #20, ao wa ko 000, ao fi we akara na, ao we
ni owu dd ati ff, ao wa jo......ewe ola ao fifon inu koko ao gbe
eye adan le ao tunfon ewe olalelori aojo..tobadini agokan oru
aolo akoko aotunlo elekeji.
129- OSHOLE
Ako alangba kan, igbo, wead,1,000, ao ko igbo yi si enu
alangba yi, ao fi igi tii wole si enu re dadaa, eo wa ko oruko
yin sara owo yen, eo roll e, eo wa ki si enu alangba naa, pelu
atare aja kan, jijo po, ni aago kan oru, oru naa nia o lo, lilo re,
eko elewe kan eo je eko yi, ao wa da eburu yen sori ewe eko
naa, ao fi ahon laa, ao mu otin le lori.
130- OSOLE AYARA BI ASE (Osole yi ma nfa ki awon eniyan lati ona jijin ma
gbo ohun tiwa kikan....won yio si maa wa wa wa si ibiti aba wa odaju gidi gidi).
Odidi ori owawa kan to ni irun, basi eran kelenu sonu tofe die,
ao ki bo enu owawa na dada, ao wa fi ewe ejinrin oojo bo
mole dada, atare kan si legbe. Jijo po. Ao ma fi mu eko
gbigbona laro kutu kutu......pelu adura...nitori bi owawa bake
ni igbo ohun re agbalu kan...ohun emi omo ni ki
gbogbo eniyan magbo nibikibi, ki won si wa mi wa loni towo
towo. Nitoripe ojo ti oku ba ku lese omo araye nda giri giri
nibe towo towo. Olowo, oloro ilu, eda giri giri wa sodo mi loni
towo towo. Ase. Sugbon odara ki a se ose ebe awon agba pelu
re. odaju. Yio ju wa se oooo. Ase.
131- OSOLE (OGUN ANABO).
Egun ibeji mejeji, eiyele meji ti won pe ni ejigberede, eyin oga
40, ewe apada 20, ewa ere 40, odindi eye igun kan, odindi
atare kan, ewe afoja ti a n pe ni lokolepon, a o ko sinu agbada
ao jo po, ao ni jo ewa ere yi mo ati eyin oga ati iye owo ti o ba
wuwa mo oo, a o wa ro sinu ap funfun, ao wa gbe lo si ibiti
won n sin oku si di ojo meje, lehin ojo keje ti a ba mu owo na
wa le, a o fi gbogbo nkan ti enu nje bo, ao ko owo yi, ao lo na. 63
N.B A ko gbodo na owo yi ku, ojo ti a ba na ku ni ogun na
baje.
132- OSOLE TODAJU
Ologbo totobi kan, ao dubu re sinu ikoko tuntun, ao gbe sori
eje yen, ao wa agbebo adie topamo dada, ao dubu re sori
ologbo yen, ao gbe adie yen sori ologbo odi jijo. Idi ikoko yen
kogbodo kan ile nigba ta ba ndubu awon elo yen, ao jo. toba
ku die ko jo tan, ao ju atare sinu re, ao ko opolopo ewe
alupaida le lori, ao jo, ao lo, ao ro sinu ado ato, ao pa agbebo
adie fun sere yen, ao mafi omi tutu lo ni ago mejila osan.
134- OSHOLE
Oga gbigbe kan an fii iru wooro ati iru Pete boo Lara Dada ao
Jo po pelu odidi atare kan,ao ra maltina too tutu daadaa so da
ebu yii si ao gbe mu lekan naa
65
le laya, ao wa gbe le ori aaro, ao jo, igi ti abati fi nro lori ina,
igi yi kogbodo kanle ti ao fi pari ogun yi ti aba jotan ori ina lao
ti lo ti yio kuna, ori ina na lao tipo mo ose dudu pelu igi ti afi
nro tiko gbudo kanle. Tia ba ti po tan, ao solale sori nkan, idi
re ko gbodo kanle mo o, ao sokale sori nkan, ibe ni ao ti ma
buwe ni alale ti ako nijade mo, ti aba ti we ose yi tan ao lo sun
nio.
66
67
AWURE
138- AWURE
Ẹran erin, ẹran ẹfọn, ewe sapo, ewe akoko, eku eda 1, odidi
atare 1, ẹyẹle funfun 1, ṣiṣe rẹ... a o jo gbogbo awọn nkan
wọnyii papọ, yatọ si ẹyẹle yẹn, a o lọọ kunna, a o rọọ sinu ado
idẹ kan, a o pa ẹyẹle yii fi bọ ado yẹn, a o gbee sinu apo asọ
funfun kan, a o maa fi ekuru funfun bọ ado naa ni every week,
a o maa fi ẹyẹle funfun bọọ ni oṣooṣu.
ofo re : agbelegbola 3×, agb'ọdẹdẹ gbayi 3×, kekere labi erin sinu
igbo ti erin di nla, kekere labi ẹfọn sinu ọdan, ti ẹfọn fi di nla, 68
edumare wa sọ emi lagbaja ọmọ lagbaja di ẹni nla, bi
ogburugburu ba lalẹ hu, a gbe arin oko igi di nla, ifa sọ emi
lagbaja ọmọ lagbaja di nla, a kii fi ewekewe joye lẹyin akoko,
eledumare wa fi emi lagbaja ọmọ lagbaja ṣe olu, ẹda ki o dari
ọpọlọpọ owo temi lagbaja ọmọ lagbaja wa bami, ẹda ki o dari
owo rere, ile rere, motor rere, etc origun mereerin aiye wa si
ọdọ emi lagbaja ọmọ lagbaja, loni ati titi laelae. lilo re... a o
maa fi ebu yii sa ori ni emeerin laarin oṣu kan.
145- AWURE
Ao wa okan malu dudu ti ko ti womi raaraa ao ki ori igun si
iho kan, ao tun fi egberun kan naira we igbo ao kisi iho elekeji,
ao wa ki atare si iho eleketa ao jo ninu ikoko tuntun ao mafi
foko mu lararo, lola bade
154- AWURE
ewe ataa abalaye, ewe ejinrin ojoo, afeloru ojoo, ao gun mo
ose dudu, ao tee iyere osun ni ifa ejiogbe pelu ofo yii ofo
olufemi olajumoke oraja taja tan olufemi loruko ti a npe iwo
ataa olujumoke loruko ti a npe ejiogbe, oraja taja tan loruko ti 72
178-AWURE OSOLE
Ori oga kan, ori aluko kan, ori odidere kan, ileke itun, ileke
ifa , abeere, ikun ojia, iye aje kan, ewe iba igbo pupa. Ao gun
papo, ti aba fe funyan. Ao fi iyanrin okun ati osa tefa eji ogbe
si Aope ohun re.
OHUN RE : Olugberere komi o, agbe nigbe ire pade olokun,
olugberere komi o, aluko ni gbe ire pade olosa, olugberere
komi o, odidere nigbe ire pade olu omo (child) odo, oba omo
ateni legelege fori gbeyi ilu loni, ki tokunrin, tobinrin oma
tunmise, ki won ma wa mowo wa fun mi, abeere loni ki won
ma bere mi tona bo ki won osi maru owo funmi wa, ojia loni
atokunrin atobinrin ki won ojiki won ma mowo funmi wa ,
orunmila bami wowo lodo okunrin ati obinrin, loni dandan ni
ti baigbo majeki rere na ope ,maje kojina, inu ile mi ni iya aje
gbe joko si. Ibe na laje gbe mawa bami , ninu ile ti mojoko si
nibe ni ki won oma mu owo ba mi, sebi igun mererin ni ilu ni ,
igun mererin naa niki won omaa mowo fun mi wa. Eniyan
pupa nio, eniyan kukuru nio, eniyan gigun nio ki won ma 78
mowo fun miwa. Ao papo pelu ose dudu ati yen Fifi we
180- AWURE
Ewe isaju, ewe oriji, ewe omisinmisin, odindi oga kan,ao jo po
mo ose, ao maa fi we.
224- OLUBASIRI
92
Odindi tagiri nla meta, ewe ajeobale, eran owo inaki igbo, oga
gbigbe 9, odindi ataare nla 9, ao jo papo ao da sini oti shinap
ao maa lo lemeta lari osu kan
226- OLUBOSIRI
Ao han suratul wakiah meta, ao lo egbo ogbo kuna daadaa ao
fi se gari re ao daa oyin igan gidi si, ao gbemu.
98
lori ruku ao kaa alamtarakahfa 25 dele, ifori kanle ekeji ina
ataina 25 lehin eyi ao toro omo ise alalubarika. ao fi akara yii
se sara fun awon omo kekeke ati agba.. walahi pelu ase olohun
ao ri awon omose naa
271- OWO.
Afin ni Oluwatomisin, ki i se eni aa gba loju.
Aro ni Oluwatomisin, ki i s'eni aa na.
Abuke Orisa ni mi nki i seni aa di ni kanin-kanin.
E j'olowo o lo o
104
272- OSE ANU
walahi unkan ise yii kere pupo sugbon ise nla ni.... ose dudu
ati ewe ola, ao gun ewe ola yen kunaa daadaa ao waa po mo
ose dudu ao maa fi we ni every wednesday, dakun ma se we
ose yii ni ojo kijo sugbon wednesday... ti enia baa fe lo sin
owo lowo enia kan, ki iru eni bayi fi ose yii fo owo mejeji ati
ese mejeji ki o to lo baa eni naa, wednesday ni lilo re o. iwo ti
o baa se aigboro ti o lo we ni ojo ti o baa wu e.
105
ASETA
273- ASETA
Igbin to pinu 3 ewe kasan eru alamo odidi atare kan ao jo papo
ao rosibi kan tiaba felo ao bu die nibe ao te ifa obara eka si ao
wa pe ofore si ao fi omi gbigbona lo tabi eko gbigbona. odaju
275- ASETA
ao han suratul masad meje sinu paper funfun kan, ao lo ori eku
asin gbigbe kan, ao fi se gari re,...... ao di ni owu funfun ao
maa ju sapo bi a baa nlo si arin awon ota ao mun tira yen dani
ao kaa suratul masad eyokan si ao ju si apo... bi awon ota baa
pe igba won koni le se waa ni jamba kankan
277- ASETA
bi enia baa lo ise aseta yii walahi talahi bi ota baa nse unkan
buruku lori eni naa, ise buruku naa yio daa si eni naa lori pada,
lagbara olohun eni naa yio waa pada confess ise ibi owo re ni
igbati inira baa mun... bi a baa forijin arare yio yaa sugbon ti
ao baa foriji walahi eni naa maa ku danu ni... ao han suratul
yasin lori podi, ao bere lati ipari titide oti bisimilahi.... ti a baa
ti nha ayah kokan ao maa fi oruko waa ati oruko iyawaa si titi
ao fi han tan, ti a baa han bisimilahi ori yasin yen ao tun fi
oruko wa ati ti iyawa si... ti a baa han tan ao gbemu, ao si paa
adie kan se sara... lo baa tan.
278- ASETA
walahi talahi emiti mo ni ise yii gan walahi emi gan koti seri,
ise ayejohun ni, ero nja re si won die, ohun ti o won ni ibe naa
ni epo ori esu... ki se epo ti won daa si ori esu ti won nbo lo
nje be oo, iwo ti o baa mo aye waa lati bere tori wipe alaye
107
epo yen po pupo. Ao waa epo ori esu die, ao kan die si owo
waa, ao lo si eti odo ti o nsan, ao bu die ni ibe ao da si ori epo
yen ao ropo, ao laa... walahi ti won baa nsa ogun buruku siwa,
walahi talahi ojo naa asu ni adugbo naa pelu ase olohun, ojo
naa atu won kaa, beni gbogbo ohunti o je unkan ogun ni yio
maa baa won jaa... walahi epo ori ogun yii ni mo nwa bayi..
mofi olohun bura mo waa ni isagham bayibayi... moti waa ni
ibe lati monday.... mo waa ni side eru oluwo bayi bayi... iwo ti
o baa ni anfani lati ri iru epo yii dakun yaaraa se ise naa... epo
ori esu ni epo ti awon ti won maa nfo eyin ni eku, ki won to se
epo yen raaraa, oni epo kan ti yio tidi epo fun ara re, epo yen
ni ao toro sugbon awon elepo won ki fun enia tori wipe o lewu
die fun won, ayafi ti o baa le san owo epo naa.... koni da fun
ota mi
280- ASETA
korowu to po daadaa, egun ti aja je ku, odidi ataare kan ao jo,
ao teni ejiogbe ao pe ofo si, ao maa fi epo pupa laa ni ojo
marun marun ofo bi ina baa sun isu jije ni fun omo araye. bi
orun baa sun isu omo araye a sonu. lodia fun eye gunugun to
108
ni ohun yio je korowu orunmila, orunmila ni ko maa je
korowu ohun, o ko o je orunmila pa ofi mun yan je. akala naa
de oni ohun yio je korowu orunmila, orunmila ni ko maa je, o
ko o je, orunmila paa ofi mun yan je, owiwi naa tun de oni
ohun de je korowu orunmila, oni ko maa je o naa ko o je
orunmila paa ofi mun iyan je. awon meteta parapo won to iya
imunle won lo, won ni awon yio se orunmila ni ijamba,
orunmila ni ti o baa se bi ise ni ki gbogbo ijamba won ko maa
se mi, ki awon ota mi ko maa le sun ko male wo, toripe bi aja
baa gbe egun a dobale gboro, idobale aisan ni ki nma ba
gbogbo ota mi. ha! ejiogbe ooooo ki o baa mi gbe gbogbo
awon ota mi lo si orun aremobo ki o ko gbogbo ire owo won
waa baa emi mutiu.... ojo ti a baa kan pere ni pere nsoje,
adigbonaku ki daa ojo iku tie dola gbogbo eyin omo egbe ewe
nje ao ni ri inira gbogbo waa ni ao bori ota waa pataaaa, bi ina
baa sun isu jije ni fun omo araye. bi orun baa sun isu omo
araye a sonu. lodia fun eye gunugun to ni ohun yio je korowu
orunmila, orunmila ni ko maa je korowu ohun, o ko o je
orunmila pa ofi mun yan je. akala naa de oni ohun yio je
korowu orunmila, orunmila ni ko maa je, o ko o je, orunmila
paa ofi mun yan je, owiwi naa tun de oni ohun de je korowu
orunmila, oni ko maa je o naa ko o je orunmila paa ofi mun
iyan je. awon meteta parapo won to iya imunle won lo, won ni
awon yio se orunmila ni ijamba, orunmila ni ti o baa se bi ise
ni ki gbogbo ijamba won ko maa se mi, ki awon ota mi ko maa
le sun ko male wo, toripe bi aja baa gbe egun a dobale gboro,
idobale aisan ni ki nma ba gbogbo ota mi. ha! ejiogbe ooooo
ki o baa mi gbe gbogbo awon ota mi lo si orun aremobo ki o
ko gbogbo ire owo won waa baa emi mutiu.... ojo ti a baa kan
pere ni pere nsoje, adigbonaku ki daa ojo iku tie dola gbogbo
eyin omo egbe ewe nje ao ni ri inira gbogbo waa ni ao bori ota
waa pataaaaa
281- ASETA
109
Ao fi ewe awerepepe bo eyin adie ibile kan ao bo mo inu eru,
bi o baa jina ao bo je... bi won baa ran ara siwa koni sise odaju
daadaa
294- "ATUDE"
Epo pupa, ao ra ape tuntun kan, ao da epo si, ti epo na batigba
dada, ao da egbo tude tadi si ona mesan, ao dasi, ati ata ijosi
topo, ati odidi ori oka kan tolase, ati odidi atare kan, tabajotan,
ao pin si ona meji, ao fi idakan po ose, ao mafi we lalale,
tabawa de, ao fi idakeji lo peak milk, bi ao se malo niye titi yio
fitan. odaju
301- ADITI ¤
Obinrin tabi Okunrin ti o baa ni iru ise yii lara, Unkan meji
kan a maa je ti eni naa, akoko ni wipe, kosi Asasi Ogun
kankan ti o le ran, ti won baa npe ori re koni gbo lailai, bi won
baa fe pe pa lati Oju orun ko ni gbo laye... Ekeji ni wipe bi
Obinrin baa lo ise yii gbogbo awon oni APE OBINRIN bi won
baa pe koni gbo, Bi okunrin naa baa lo Bi won baa fe lo ape
fun won won koni gbo... Iru won ni won maa npe titi ti won ko
ni gbo Ape iferan.. esawuru meta, ewe Apada meta, iyepe die
ti o waa ni isale bata ese osi waa ao jo pelu Oko Ataare kan,
gbere meta meta si egbe eti Mejeji, enia pupo le lo
115
302- TI OGUN BAWALARA OBINRIN>
Ao lo wa ekolo eyikeyi odidi kan ao lo eyo atare kan mo ao fi
singbere yipo idi wa.
N.B. : Ti magun bawa lara obinrin oko wa koni gbera dada, ti a ba fe
guo ori obirin na, ko wa yio wale, tested ok
311- STROKE¤
Ewe Ato, Eru awonka, ori, ao fi ori yii tele agbo ao fi eru yen
le lori ao fi ewe ato le lori ao fi omi se jina daadaa, emeta ni 118
mimu re lojumo.
322- KI OGUN AFUNJE OJU ORUN ATI OJU AIYE MAA LE SISE
LARA WAA BI AWON OTAA BAA FUN WAA JE, TABI KI A FI
YAA IGBE DANU BI A BAA TI JI NI OJO KEJI
Odindi agbon kan, ao jo omi re sinu cup kan, ao waa daa epo
pupa sii. Ao fi sibi popo daadaa. Ao gbe mu, edakun emaa
gbagbe awon omo ati iyawo yin naa ooo.
345- ARIRAN
128
Ao wa Ewe tete abalaye ao tu tegbo tegbo ao jo pelu odindi
ataare kan ninu ape ejoogun tuntun ao da si ona meta ao lo fun
ojo meta ojo akoko epo pupa ni ao fi laa Ojo ekeji ori ni ao fi
laa Ojo eketa adi ni ao fi laa,
Gboloun yi ni ao ma filo ao maa ba soro bayii Arina ti mo loyi mo fe
ko sise osan o, ise oru ni mofe komase funmi gbogbo nkan
toba fe sele ni kin mama ki o si maa yemi daadaa Akiyesi ki
ise yi le sise dada e lo Ebe Agba iyonu dada
369- MOKOLE
Ao wa ewe ako ibepe tutu, eru kan, ao koko gun eru na ti
okunan dada, ao ko papo ninu igba, ao wa gbo pelu omi die,
ao wa re ewe na danu, ao wa gbe eyo igbale meji sori igba ti
omi wa ( to form cross on top of the calabsh ) ao f'owo mu
dani ti koni jabo, ao gbe omi na mu be.
377- ATOSI¤
ao wa odindi epa ikun, odindi bara kan, akokanhun, baka , a o
fi emu da lagbo, a o gbe pamo fun ojo meta, a o ma yo mu
lehin ojo keta. Atosin naa daran.
136
378- AGADAGODO¤
Ao wa awo ekun, awo egbin ori adaripon kan, ori pepeye ati
esere mejeji, ao Jo po, ao fi owu dudu ati owu funfun Di po
mo ara agadagodo, ao pe ofo re si ao wa ti pa, OFO RE,,,
agbin sinu ni egbin gbin, akun sinu ni ekun ku, ori ti adaripon
bale ki fi ba ogiri soro, igbagbe se eledumare ko la ese pepeye,
owu dudu ati owu funfun won ki jara won niyan, ki lagbaja
omo lagbaja ma jami niyan loni o, ao ti pa
384- AJEGUN
Ao wa oga oye kan, ao fi ako Okuta ge iru oga yii ni oye, ao lo
pelu omo atare mesan (9) ,ao fi si gbere yipo owo wa mejeji.
385- FUN EYIKEYI BUKATA¤
Ao waa Eso Dabinu 41, ao maa kaa Ipari Suratul Wakiah ati
Suratul Rahamon papo ni 41 times si eso kokan, ao kaa si
gbogbo re pata, ao maa je eso naa fun 41 days ki a to sun ni ale
411- ATOSI
Ao toju Bara nla kan, ao wo gbogbo omo inu re danu, ao be
epo ara re pelu ao waa ge si wewe sinu Ogidi emun tabi omi
Oronbo ao daa Kaun bilala si.. Lehin ojo keta ni ao mamu ni
Gas kekere kookan lararo.
414- AWORO
Agbon nla kan ao lu Ori re ni ona kan ao daa omi renu, ao lo
ewe Awerepepe kuna, ao ro ewe ti a lo yi sinu re pelu ito idaji
ti a to ki ato soro si enia kankan ao daa sinu re, ao di unkan di
lenu daadaa, ao lo ri mo arin gbungbun shop waa. Odaju
ase....
423- AWORO
Ao wa tagiri nla kan, aoha gbogbo aje arare, aopo mo kafura
pelebe, aofi ose die ko, aofi ka tagiri yi loke, aoso mo oke enu
ona, opari, ewe amo jeooo, (olujide 1) 08060242749
424- AWORO Lati owo Abubakar Damilare Olujide,
Ao wa akerengbe kekere kan, aofi owo eyo tio luju kan si, aofi
igi akoko to gun sedede ika arin sinu re, ao bu omi si ao gbeko
si enu ona ile, ao ma bu omi si ti ti inure bati gbe, ewe amo
jeooo,
425- OLUGBOHUN
Ao jaa ewe Abamoda oni iga marun ni ona 16, ao gun po mo
ose dudu ao waa iwo Malu ao ko Opolo oye sinu re pelu Eja 147
ojiji oye, Alakan Oye, Oga oye ati ako Alamun oye sinu re. Ao
waa fi Ose ti a gun yen bo lori, ao fi owo eyo ti koluju te
Ejiogbe si lori (Ori ose naa) ao waa lo kan oje oro Agogo si ti
yio dun daadaa, ao lo ri mo ile ninu igbo, ojo mesen ni yio fi
waa ninu ile naa, ao daa koko (Pot) nla bo mole, eyin ojo
mesan ni ao lo wu... Odililo
439- AWORO
Ewe Rinrin Ogede Omini 16, eyin Ibile 16, ao jopo ao lo
kunaa daadaa, ao maa fi Omi Aye lo lararo walahi o daju
443- ATOSI
Ao wa bara odidi kan ao wa fi obe ha gbogbo ara re danu ao
ge kekeke lehin igba ti ati yo egusi inu re danu tan ao wa omi
osan orombo ti atun masi omi osan wewe ati kanhun bilala die
ao da gbo re po sinu ike olomari fun ojo meta lehin ojo keta ao
mamu ni sibi imuko meta lojun mon.
445- AJEGUN
Owo alangba mererin eyo atare 7/9 epo obo die ao jo papo ao
fi singbere yipo orun owo wa mejeji Mojuba awan Agbagba
odaju
446- IWOSAN FUN EGBO ADAJINA
Alubosa elewe, aidan, Fofo okun,( Oku Okun) ayu 'kanafuru'
eru awonka, imi ojo die, ao gun po, ao sa yio gbe daada, ao tun
gun, ao ku ni ajo yio kuna daada, ao ma bu sibi kankan sinu
eko gbigbona, ao tun bu adin eyan die si eko na, ao po papo,
ao maa mun laro. Olorun loni wibe jebe EYONU AYE! Ewe
rerinkomi, eyin ope ibile kan, padi atare kan, ao jo papo, ao
mafi oyin lo, tabi kia daa sinu oyin ao maa la larolaro.
152
ODAJU!
447- AJEGUN
Egbo lapalapa ati odidi atare kan ao jo ao lo ao ma fi epo pupa
la, lalale odaju
454- OWO
Ao gbe Orogbo kan mi ao waa yaa mo igbe ao saa gbe daadaa
ao di ni ikobere pelu eyo atarre kan ao waa pani awo funfun ao
maa fi si araaa... Enikan ki siwo na imi
455- AJEGUN
Ao waa Egbo lapalapa funfun ao jo pelu Odindin ataare kan ao
153
maa bu ebu yen sinu awo sobi pelu epo pupa ao maa la ni ale.
458- ADODUN
Ewe amunimuye, Abere, Ewe Awerepepe ao lopo mo oyin,
obinrin yio maa fi pa oju ara baa okunrin sun,, okunrin naa yio
maa fi paa oko baa obinrin sun
459- AWORO
Eyin Adie ibile meji, odindi ataare kan ao jopo ao ro sinu ado
ato ao so ko si oke ile itajaa sugbon ao maa bu omi si lojo keta 154
keta 3-3
462- AWORO
466- KI A LE RI ALANU
Egbo ati Ewe Lapa funfun ao gun pelu Erinje die ao gun mo
ose dudu ao maa fi we lori ijoko ni alale
470- OWO
Ewe eyinolobe, ewe orijin ao lo po ao sa si ategun ao ra ni
ikobere pelu awo idi mere ti aba fe jade ao so wipe LEHIN
LEHIN LOLOBE NSO
471- OGUN MAGUN
Ewe ailu 7, Eyo ataare 9 ao lo po ao ko sinu eyin adie pelu
Oruka meta ao wa se jina ao je eyin naa ao maa fi oruka bowo
Ao fi ida keta : ao da sinu awo funfun ao we ni tira pelu owu dudu ati
pupa, ao fi aso pupa ran ni olounde ao wa fi owu ibile dudu ati
funfun we round ti olounde yen ko ni han jade, ao ma wo si
ibadi, after 7days ti aba ti fi ose yen we ni ao ma wo siidi.
Akiyesi: ao ni je ki omi kan oju gbere yen fun ajo meje gbako, amo ele
ma shin apa shin ese. Ao si ni ma fi olounde yen we, ao ma bo
(remove) ti aba fe we.
483- EDIJA TO LE
Aiku Alakan, Aiku Alagemo, aimoye eyo Ataare, Ewe
Esinsin; Ao ko Ataare le lori ninu igo pelu Alakan pelu
Alagemo naa gba 7 days; Ao si lo fi emuna ko Ataare na, ao
159
da si ile Ile eni ti a ba fe ba ja.
ofo re : Esinsin kii kere ko ma joni. Ao ba oogun na ro ejo ohun ti a fe
ko sele ninu Ile naa.
NOTE : Enikeni to ba fi oogun yi se ika, ile yio mu.ase.
488- ISOYE:
Ao wa oju (Ade) oro ati osibata, ao jo mo atare kan, ao wa da
sinu oyin, ao ma fi mu eko laro laro
489- ISOYE...
Ewe abiwere, ewe woko,guluso 9 jijo po ao fifo komu tutu mu
otan.
490- ISOYE...
Ewe abiwere, ewe woko, guluso 9, jijo po, ao fifo ko tutu mu.
Otan
491- ISOYE:
Igbin to gbonu1, Odindi Atare1, a o yin atare yen, a o fe 161
pantiri re danu, a o ko si oju igbin yen, a o fi ewe Iran di, a o fi
si egbe amu fun ojo mokanla, bi ojo re ba pe, a o sa atare yen
si inu orun yio gbe. Agba yi o ma lo eyo meji, omode eyokan.
Ewo re: A ki gbodo juwe Ogun isoye fun eniyan mo.
501- AGBELEPOTA
Eyin ibile kan, ose, ao fi owo(hand) gbe eyin na si ori wa, ao
wa se adua bi ase fe, ao wa je ki eyin na jabo si ile lati ori wa
kio fo po si ile, ao wa fi ose yen ko tepotepo ao Popo daada, ao
wa ko ose na sinu ike funfun kan, ao ma we ni emeji losu.
Odaju. Okere gan sugbon ise gidi ni yio bayin lara mu ni
agbara Jehovah.
502- OSE ISEGUN TIN DA IBI PADA SORI ONI BI
Eru oju aro, iyo, ao bu eru na ni won ba ati iyo na ni dede eru
tia bu yen, ao po mo iwon ba ose ti ale we tan le kan so ao fi
we, ao ma we be ni emeji losu. Odara pupo o. Eni da eru ni eru
to. Yio ba yin lara mu ni agbara Jehovah.:
503- AFERO.
Ewe tagiri,aso funfun,a o gun papo pelu ose dudu,a o tun ran
aso funfun ni asurun,a o Kan iso mo oke,a o ko ose yen si ninu
163
ti o ba di ojo keta,a o ma bu ose yen ni oke a o ma fi we pelu
gbolohun re : Girigiri niti tagiri,a ki juwe alaso funfun ki a to
ri,atokunrin atobinrin e ma wa raja lodo mi o,towotowo ni ki e
ma wa oooo. Odaju
520- ISORI
Iye agbe 1, iye aluko 1, iye odidere1, epo apa, epo iroko, epo
ose, epo oruru, odindi atare kan; jo gbogbo re po ro sinu sere,
ao pa akuko adie funfun kan, a o fi eje re pa sere lara, ao tu iye
re die pelu si lara 166
Ofo re:
won pe ori agbe, agbe da aro kun aro
won peri emi lagbaja omo lagbaja moni owo kun owo
won pe ori aluko, aluko ko osun mo osun
won peri emi lagbaja omo lagbaja mo se rere kun rere
won pe ori odidere, odidere se iko yebeyebe
won peri emi lagbaja omo lagbaja moni aso kun aso
won peri ose, ose fi sora mo ora
won peri emi lagbaja omo lagbaja moni ola kun ola
ti omode ba dari so apa, apa a pa
bi agba ba dariso iroko, iroko a ko,
bi omode ba dariso oruru, oruru a rulo
ao da aniyan re si.
555- IDAKOLE
Ododo Asunwon Oyinbo, ao sa ko gbe daada, ao lo kahun die 173
pelu e, ao ma fi ogi gbigbona mu ni sibi kan laraaro.
603- ITAJA:
Ewe abo, awo eran eyikeyi eo jo mejeji po, ile oja die eo lo po
mon eo da sinu ipara kan eo ma fi para.Ofore:bi awo bawonu
ina wiri wiri abo, abo ni nbo oloja loju ni nfi oun owo re tore,
wiri wiri lero nbo oja.
611- AKOYA
Ao wá akọ òkúta, virgin paper, òwu dúdú àti colour miran, ao
ko orúkọ ẹni náà tàbí ìyè wọn sínú paper yẹn, ao lè mọ ara akọ
òkúta náà, ao fi òwú méjèèjì fi wé títí paper náà kò fi ní yọ síta
mo rárá, ao ra ìgbà olomori, ao kò orúkọ tiwa sínú rẹ, ao bù
omi sínú ike oda tàbí ike custard, ao gbé òkúta tí a wé yẹn sínú
omi inú ike náà, kí omi náà bó pátá pátá ni ó kí a wá depa síbẹ̀,
ale gbé sì abẹ bed wá tàbí ayekaye nínú igun ilé wa, gbogbo
àwọn tí ó orúkọ wón bá wá nibẹ wón ó ní jẹ́ alátakò fún ẹni
yẹn láéláé ayafi ti o ba tú ìṣe yẹn loku, ó dájú fún ẹni tí ó bá
wà láàrin ọ̀tá alátakò.
623- EKETA
Patako ese maalu , a o sun ninu ina , fi fi fo eko tutu mu
624- EKERIN......
Alubosa ayu, ewa funfun, a o se po ti omi ewa yio gbe mo
lara, a o je , si se ni gbogbo igba.
625- EKARUN
Ewe ajeobale, a o lo po iyere , a o ma fi se eran elede fun eni
na ni gbogbo igba
626- EKEFA
Opolopo egbo akoogun , opolopo alubosa ayu , a o pa alubosa
yen pepe , a o ko sinu omi iru , a o fi kafura bi meji si , mimu
ni short kan leyin ojo keta laaro lale.
627- EKEJE
Opolopo alubosa ayu, Atale pupa ati funfun, Egbo akoogun
lopo, Afoomo igikigi
A ko sinu ike , a o da awon eleyi si, Shinap gidi, Oyin gidi,
Adi eyan, Omi osan were
A o se won ni deede kan nan, a o da le lori, leyin ojo keta,
mimu ni emeji ojumo
628- OGUN IBON
Ekuro OJU ona 16, ewe ailu 16, odidi agbon tojabo funrare
kan, ao jo pelu odidi atare kan. Ao maa fi foko mu
laaro.Tiwon ba yinbon siwa, ota ibon o maa gbon sile lara wa
ni. A le dasi adie lenu ka yin bon si wo.
631- ISORA
Ao da ounje okele ti ale je tan si ori olota pelu obe, ao wa pe
Ohun re si. Ota nlanla titi sanmo bosile aye, o gbo hai tagiri loruko
tanpe Iwo ile, oso nibe nile tin deru ba emi L omo L ile pa, aje
nibe nile tin deru ba emi L omo L ile, Emere ni, alfa ni, pastor
ni, woli ni etc niba be nile tin deru ba emi L omo L ile pa
gbogbo won. Ko ju belo sugbon olagbara.
632- IMULE
Eyele eyikeyi, Aoge apa re mejeji laye, aoko apa mejeji yen
lori ara won ninu agbada, aofi awo ekun le lori pelu edan tako
tabo, aojo po. Aolo kunna. Aowa naro awon edan mejeji yen
segbe ebu yen pelu owo osi wa, aofi owo otun gba awon edan
yen lori lemeta, Aowa sope.
Motidi imule loni oo 3x, wiwi ekun opanrangandan 3x, aiwi
ekun opanrangandan 3x, odifa fun nana tisawo won lode
esumoba, emi eleye, eyin eleye, eleye kiba eleye ja, eleye kiba
eleye binu, eleye kiba eleye wijo, emase bami ja, emase bami
binu, emase bami wijo, ewa sina owo nlanla fun mi (adua).
Aofi ebu yen fokomu lekanna ni. Aowa ko awon edan yen
sinu apo aso funfun kekere kan, aoma fi rori sun.
654- ONMO
Ewe Alupaida to ni eso, Atare odidi kan
Lilo re : ao lo papo, ao ma fi foko mu ni ihoho ni ale ati aba fe sun.
655- AFORAN
Ao waa awo Igala to fee daadaa ao jo pelu Odindi ataare kan
ao lo kuna ao ro sinu ado kanm ao gbeko kogbodo kanle mo..
Bi a baa fe lo ao bu die si owo ao teni ejiogbe pelu gbolohun
yii
Gbolohun : Eru ku owo egbe 3x Iwofa ku owo Olowo re rorun Alakeji
3x Won sa omo Alake laake 3x Won taa Omo Olofa lofaa 3x
Won yin omo Oyinbo ni ibon ni oran bade 3x Won ranse pe
etu beleje inu igbo kowaa ba won tan Oro naa, etu beleje inu
igbo de kori oran naa tan 3x Won ranse pe efon gagara ile
odan ko waa tan oran naa, Efon Gagara de ko ri oran naa tan
3x Won waa ranse pe Agbonrin abiwo lori sarasara ko waa tan
oran naa, Agbonrin Abiwo lori sarasara lo de logbon oran naa
danu lori Lagbaja omo Lagbaja. Ori Lagbaja omo Lagbaja ko
Oro ejo (ao daruko Ejo naa ati awon ti won nba waa fa oro
naa) ao niki o baa waa gbon daanu ko maa lojutu mo ao waa fe
danu. 196
656- OFO-AFORAN
Adan o l'ori ade, Igbin o l'orun ejigba-ileke. O da ko Adebori ti
ise yeye adan, t'o b'aro lomo sori igi. Oun ni Afomo!, Afomo o
l'egbn, ori igi ni i gbe. Beeni igi tio ba si fi ti afomo se, afomo
naa nii pa!. Orunmila ni nje oro yi di kaka-ngbasa, mo ni o di
onigikigi. Ifa ni "Igikigi kii maa ba Asunrin fori gbori. Eyin
adie ki i dariso okuta, igbin kii dariso iyo. Ina ki i dariso omi.
Owo koko l'a fii wo igi. Owo orisa la fi i wo imole. Kujore
Oluwatomisin ma di eni owo, E j'olowo o lo o.
703- ASINA : Omo Yahoo lelo lati ri new client tomama sanwo e
dede, tio ni ni aroye ninu.
Ao fi owo nla tuntun ilu ti abawa tele ape. Ao se adua si
lopolopo. Odd ori ofafa tonirun kan. Ao fi iru-pete round ara
ori yen, ao tun le eso-werenjeje agolo kan mon Lara, ao gbe
sori owo yen ninu ape, ao fi odd atare kan si legbe otun. Odi
jijo. Ao lo kuna Dada, ao ro sinu igo ff.
204
Lilo re : Ao mix oyin-gidi pelu milk papo,ao da gbogbo ebu yen si, ao
malo laro laro kistosoro siyan. Hasibunalahu
704- ASEJE AWURE ONI SUYA, O TUN SISE FUN AWORO,
O MA N GBENI PADE AWON EYINYAN GIDI KAKIRI
AIYE !
A o pa eyele ff kan, a o tu gbogbo irun ara e danu, a o ge
igbaya re, a o se yen leni(i.e No1) a o wa ge eyi toku si meta,
apapo re ma je merin(4) pomo igbaya yen. A o wa igi kan a o
gbe enu e somusomu bi opa igi ti awon gambari fi ma n sin
suya yen, a o wa fi sin awon eran eyele ti a ge si merin yen po.
A o wa taa tinaa, bi awon hausa se ma n se suya yen , a o lo
ewe Aje, pelu iyere a o fi epo pupa popo a o fi iyo sii, a o wa fi
iyere osun tefa IWORI-OBARA, a o pe ohunre si, a o dapo mo
awon ewe ati epo ti a popo yen, oun la ma da si eran suya yen
lori ina , ao si ma yi pada lori ina ko ma ba jona.
OFORE: Ibi kete ni won kole ogun sii, Ibi perepere odo ni won kole
óbalufon si, peregun susu ni won fi kole temi demi ooo,
Alaagboro-wo, Alaagboro-wa, Alagedegede-mu-petu komi
ooo, peju la n pe Aje ooo! Obaragiri, ifa kowon leyin wa ba
emi L omo L towotowo , owo won loni ooo, awon olowo,
olola, oloro ile yi, lokunrin lobinrin, obaragiri ifa ko won leyin
wabami, obaragiri, ifa kowon leyin wa bami Awon ara ilu
oyinbo , obaragiri etc...hmmm ise inu ile.....todaju ni, kai!
Ogbon awon baba wa o ni pare lealae...e danwo ojo ti eba ti je
leyin na o ti ma pe, ire de!
ELEYI NI ODU IFA IWORI-OBARA
0 00
00 0
00 0
00 00 Iwori lotun, obara losi
705- ISE YI DÁJÚ PUPO PAAPA JULO. FÚN ENITI OBAN
SISE ILÉ. KIKO LOWO, TÍ Ó WÀ Ń RETÍ BIBO ASIRI
LÓRÍ ILẸ̀ . NA,
Alabahun 1, Igbin tobonu 1, Ewe abamoda 201, Aogun po tí
yíò kunna. Ao sa tí yio gbe. Ao tun gùn tí yíò kunna, tí yiodi 205
powder. Ao ma bu die die si inu isasun. Ao ma. Fi ṣe èdo malu
tí agesi 16 jẹ́ ní ọjọ́ méje-méje sì arawan, wallahi odaju. Ti
onitoun yiofi parí bukata towa ni waju rẹ koni rahun owo.
706- FITILA TI ANFIN PE ARISIKI WO INU ILE TI ANGBE
Eja aro ojúlówó gbígbé 1, Iru ìdí ẹyẹ oge, Oga gbigbe 1, Ewe
eṣinṣin funfun, Omoloju aja mejeeji, Ori oromodie 2, Fitila ńlá
olójú 16. Ao jo wan papo. Ao lo kunna. Ao da sì inú fìtílà yi.
Ao te ni ifa odi méjì. Ao wa ṣe owu akese gege bi owu àtùpà tí
yíò gùn díè sì ona 16. Ao fi si ojú kokan, nínú fìtílà yi. Ao da
epo pupa lè lórí. Ao ju ori (shealbutter) sì inure. Ao ma tán iná
sí ojú merindinlogun fìtílà yi ni ale tí aba fẹ́ sun maju má. Ti
aba tí tàn, ao bere sì idi re. Ao ma tọrọ wípé kí Awan toni ike
ayé ìdarí arisiki nlanla wa si inu ilé na. Kí ama ṣe rahun owo.
Ao wa lọ sún. To ba tun di ní ale ọjọ́ kejì, ao tun sebe, ba yi ni
ao se tí yi o fi pé ọdindi ojo meje.
Pelu ogo oloun, ao ni rahun owo má nínú ilé tí aba tán fìtílà yi
si odaju.
707- OGUN FUN ENITI AWAN AJE NDI LOWO TIWAN
OJEKI OROJUTU SI ISE OWORE
Eiyele funfun 1. Ao pa. ao ge si 16 sínú isasun tuntun 1, Oga
gbigbe kan, Eso idoro ẹyọ 7/9, Omo ayo tiwan nta dada 1,
Ekisa ori Akitan niwanba díè, Afoma ori àpáta niwanba die,
Ewe ajeobale 7/9. Ao lo Awan kini yi papo. Ao fise eiyele yi
je pelu epo ati iyo pelu iyere 16,aose jina, tobati tutu, aofi
iyere osun te ifa OSA eleye méjì, aope ofo yisi aowa koje, ní
àlè ni aoje obe yi.
OFORE : Adìye wéréwéré ni oruko ti anpe aje, ilé Ado abiye
foroforo ni oruko ti a npe aje ile ìfẹ́. Èmi lagbaja omo lagbaja
fi OSA méjì bayin mule loni. Eko gbodo dami má lailai.
Nitoripe omode ìlú kí ìbínú fi ayo ṣe ìlà eewọ ni, agbagba ìlú
wan kí ìbínú fi idoro ṣe obe, eewọ ni, aje ayé kan wan kí ìbínú
kiwan fi Oga ro EFO, ọmọ aráyé wan koni bínú títí kiwan fi
akisa ori Akitan rán aṣọ, aje kí ìbínú kiwan balẹ ori igi aje
obale, aba tí alagemo bada ni orisa oke ngba, gbogbo aba tí
èmi lagbaja omo lagbaja bada niki òrìṣà òkè gba.
Aowa ṣe oniruru adura sì, àti ona ti Awan agbalagba ngba
206
Dínà mawa boya lórí ìṣe wá tikoni ìlọsíwájú ni, abi ìṣòro kan
ni adoju kò ní àsìkò na,
Pelu ogo oloun tí aba gbiyanju ju ti aje ni ose kini tí atun je ni
ose kejì, tí àwa. Jẹ ní ose. Kẹta, pelu ogo Ọlọhun tobaje pé
Awan agba niwan bá. Wà nìdí oro wa wallahi wan yiofi wá
lorun lè, tí ìṣe wá yioma lọ dede.
708- [1] WEGUN WEPE, TOTUNSISĖ ITUSILĘ TOGBONA..
Odindi igbin kan, Ewe alupaida, aogun mo ose aoko sinu ęru
oko tiwon tifi roko dada aomafiwe lalę Katosun...
[2] Ako Alangba aiye, epo obo, esuru, gigun mosę dudu wiwe
lori Ada tabi rim motor..
[3) Ewe peregun omunu ė 9/7 aosu losuka aofi Osun, efun,
pelu odidi atare kanjopo, aopomose dudu aowa kosinu apere
kekere Kan, aokunleti aose adura si..
ÓRÒ... Botiwu koloko pęto peregun nirehin ręę Emi--omo--
niki rehin Gbogbo abinu eni ati óta, epe waju epe eyin kinbori
ę loni oo Gbogbo egun arami kokuro patapata loniooo...
N. B. wiwę lalę patapata nioo, akogbodo ri eniyan mô ooo.
Ewo NIO
709- ETUN GBA EGBE TI NGBE ENIYAN LOSI ILE
NITORI OJO EWU
Ojo ti a ba ti ri ibiti ejo oka bati sebu si, ao pa. Ao ge ori re.
Ao ko oruka eyikeyi iyekiye si lenu. Ao wa ri mo ibi to sebu si
ti a ti pa yi. Ao wa sokun mo ara e toku. Ao wa woo wasile.
Ao wa sun nina. Ao lanu re. Ao ba awon oruka yen ninu re
otidi egbe niyen. Ki a ma fi bowo. Ewu ao barawa nile. Eti ri
nkan nkan nbo. ao wa ge die Lara re ao se je gbogbo eni tobaje
nibe lolelo oruka na odaju.
710- OHUNMO TODAJU
Ewe ogbo, ewe iran, ewe omon, yerepe gidi, odidi atare kan.
Ao jo ti a ba fe lo. ao te die sinu owo osi pelu ejiogbe
...ha,ha,ha, ede oyo kojotegba tegba kojo toyo odifa fun
orunmila oojo ti felomo ohun ti komo wo ilu re won ni boni
yiose ma mon oni omon ni yiojeki ohun ma mon won ni boni
yio semagbo oni ogbo ni yioje ki ohun magbo won ni boni yio 207
semari oni iran ni yiojeki ohun ma ri won ni boni kose ni sun
asunpiye oni tosan toru yerepe kisun asunpiye emi lagbaja
mofe mo inkan bai ao wa fi owo osi fi fo pelu eko elewe odidi
kan ao gbemu ni ihoho lago kan oru odaju ebere ibere
tiobayeyin madayin lohun.............
749- Aworo
Ewe ogbo meta, ao gun po mo ose dudu,ao le mo ara amu omi, ao ma po mole
lararo
751-Eyonu aye.
Eepo obo, imi ojo, iyere, ao lopo, ao da sinu adin eyan, ao ma fi para.
756- ATOSI
.Ao toju Bara nla kan, ao wo gbogbo omo inu re danu, ao be epo ara re pelu ao waa
ge si wewe sinu Ogidi emun tabi omi Oronbo ao daa Kaun bilala si.. Lehin ojo keta
ni ao mamu ni Gas kekere kookan lararo.
215
758- Aworo.
Ifun akuko adie, ako alangba 1, ewe sawerepepe, odidi atare kan, aa wa ko gbogbo
re sinu akeregbe kekere, a awa da iyo le lori, a wa fi aso funfun di lenu, a wa so ko si
enu ona abawole.
760- Osole.
Ipe ire mesan, odidi ejo kan, odidi awo lili kan, padi atare kan, a jopo aa lo kuna, a
ma fi foko mu lararo.
761- AFUNJE
Awo Ewure dudu, Ewe Amunimuye, Irun Abe, ekana owo mewewa ati ese
mewewa, irun Ipenpeju die, irun Ori die ao jo pelu Odindi ataare kan, ao maa fun
enia je.
767- Awure.
Ori ikun kan, ori agbigbo(dododo) kan, padi ataare kan, ao jopo ao ro sinu ado ide.
Lilo re> Ao bu die si owo ao pe ofo re so ao da senu ao fi hot sin Ofo re> Agbigbo
oma kuu eru o (3ce), ikun(remi) loni ki efi owo owoyin kun owo towa nile(mido),
ikun loni ki efikun owo mi