You are on page 1of 2

Ifá pé kí eléyìun ó rúbọ nítorí obìnrin kan, kó rúbọ fún aboyún kan; bẹ́ ẹ̀ kó sì tún rúbọ ọlà

lẹ́yìn odi tí ń lọ. Ifá pé òun ni yóò ba se ilé ayé rẹ̀ tí yóò fi gún gẹ́gẹ́. Ifá pé ire ọlà àti ìfà jíjẹ
fún eléyìun. Kò bọ Ifá pẹ̀lú eku, ẹja, àgbébọ̀ adìẹ àti ewúrẹ́ kan.
Ṣe níní - Ṣe níní
Ṣe nìnì - Ṣe nìnì
A dífá fún Ọ̀rúnmìlà
Ifá ń ṣ'awo lọ sóde Ìbíní
Yóó lọ rèé fẹ́ Sọmúròrò
Tíí ṣe ọmọ Olú Ìbíní ṣe aya
Șọmúròrò yóó lọ rèé lóyún Alápèéṣìn nínú
Oyún inú dé igbá eléku
Ó ní òun o jẹ eku
Oyún inú dé igbá ẹlẹ́ja
Ó ní òun o jẹ ẹja
Oyún inú dé igbá ẹlẹ́yẹ
Ó ní òun o jẹ ẹyẹ
Oyún inú dé igbá ẹlẹ́ran
Ó ní òun o jẹ ẹran
Èǹmọ̀ irú kín lèyí
Wọ́n lọ rèé késí
Idu níí sọ níbi hále-hále
Wọ́n késí Ọ̀pẹ̀ Àgùnká
Ó ti ní ìrègún ju àgbọn lọ
Ọ̀pẹ̀ Àgùnká níí garùn gaṣẹ̀
Ọ̀pẹ̀ Àgùnká ó ṣunwọ̀n
Ó ju àgbọn lọ
Àwọn ló ṣefá fún Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Níjọ́ tí ń sunkún òun ò lájé
Níjọ́ tí ó ń sunkún òun ò níre gbogbo
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ọlá Ifá lèmí ń jẹ
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ifá mo ra eku lọ́jà
N ò sanwó
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ọlá Ifá lèmí ń jẹ
Mo ra ẹyẹ lọ́jà
N ò sanwó
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ọlá Ifá lèmí ń jẹ
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Mo ra ẹyẹ lọ́jà
N ò sanwó
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ọlá Ifá lèmí ń jẹ
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Mo ra ẹran lọ́jà
N ò sanwó
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ọlá Ifá lèmí ń jẹ
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Mo ra ọ̀tọ̀tọ̀ ènìyàn lọ́jà
N ò sanwó
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ọlá Ifá lèmí ń jẹ
Òdògbò-nìkẹ̀rẹ̀
Ire ni o!
Ọ̀kànràn Ọ̀yẹ̀kú (Ọ̀kànràn Àìkú)

You might also like