You are on page 1of 62

1

TABLE OF CONTENT
 ORO ISAAJU
 ALAYE LORI PLANETS TIA NI
(I) PLANET SUN
(II) PLANET MOON
(III) PLANT MARS
(IV) PLANET MERCURY
(V) PLANET JUPITER
(VI)PLANET VENUS
(VII) PLANET SATURN
 ITESIWAJU LORI ORO AWON IRAWO MEJILA TIA NI ATI BIA SELE BA WON GBE
YALA LOKUNRIN WON TABI LOBINRIN WON.
 ARIES - MARCH 21 - APRIL 19(IRAWO INA)
 TAURUS - APRIL 20 - MAY 20(IRAWO IYEPE)
 GEMINI - MAY 21 - JUNE 20(IRAWO AFEFE)
 CANCER - JUNE 21 - JULY 22(IRAWO OMI)
 LEO - JULY 23 -AUGUST 22(IRAWO INA)
 VIRGO - AUGUST 23 - SEPTEMBER 22(IRAWO IYEPE)
 LIBRA - SEPTEMBER 23 - OCTOBER 22(IRAWO ATEGUN)
 SCORPIO - OCTOBER 23 - NOVEMBER 21(IRAWO OMI)
 SAGITTARIUS - NOVEMBER 22 - DECEMBER 21(IRAWO INA)
 CAPRICORN - DECEMBER 22 - JANUARY 19(IRAWO IYEPE)
 AQUARIUS - JANUARY 20 - FEBRUARY 18(IRAWO ATEGUN)
 PISCES - FEBRUARY 19- MARCH 20(IRAWO OMI).
 ALAYE BI ORIGUN MERERIN SE SOMO IRAWO KANKAN.
(I) ILA-OORUN (EAST)
(II) IWO-OORUN (WEST)
(III) GUSU (SOUTH)
(IV) ARIWA (NORTH)
 TABILI IFE WIWO
 TABILI IRUFE AISAN TABI JAMBA TI YOO MA SELE EDA
 TABILI OJO KANKAN PELU MALAIKA TIRE
 TABILI IRAWO KANKAN PELU MALAIKA TIRE.
 ASIRI TO PAMO SINU ONKA
 IDUPE

2
ORO ISIWAJU
Mo dupe Lowo Olohun oba Oga ogo, Allahu,Elohim,Edumare to fun mi ni, anfani lati wa imo yi,
tosi yanda re fun mi, lai si idiwo.
Lotito opolopo ojo loti ro ti ile si ti fa mu, amo modupe lowo Olohun wipe Mo wa laye, mo si wa ni
aiye rere. Ope ni fun Olohun.
Opolopo awon nkan ni yoo ma sele si eda laye, to si je wipe ninu akosile lowa, amo latari wipe awon
eniyi ko mo wipe oro na nbe ninu iseda won, won yoo wa gbe oro na lo si ibi ti koye ki won ro lo.
Emi a maa so oro kan oo wipe, imo wiwa yoo ma se alekun itosona fun eda laye. Ti eda basi ti wa ri
imo na tan, iwo omo iyami, gbinyanju lati polongo re fun aiye, ki araye le tun mo wipe oun to pamo
sinu aiye ju oun to fi oju han lo.
Gbinyanju ko ka iwe yi lati oke dele, kio wa wo oye re sinu oro aiye re, kio si mu eyi ti yoo ma se
itosona lori emi re.
Lotito, imo mi yi kere pupo, amo kosi bi Olohun se le se ore fun awa eda to, a ko gbodo wipe ore na
kere, tori opolopo eda lo nbe laye ti ko ri iru anfani ti emi ri yi.
Imo ko pin si bi kan, gbogbo asiso ati asite ti nba nbe ninu iwe yi, emo wipe owo mi loti wa, tori kosi
eda kan laye yi to koja asise. Mo si be Olohun fun Gbogbo oluka iwe yi wipe, ki Olohun fi agboye re
fun wa Ameen.
Eyi ni ari lati inu iwe mimo mejeji nipa asiri eso oju orun:
Qur'an 16:12:
Mo te oru ati osan lori fun yin ati orun ati osupa (planets) ati awon irawo ti mo te lori ba pelu ase mi.
Dajudaju awon ami mbe ninu eyi fun awon ijo ti nse lakaye.
Qur'an 15:16:
Atiwipe dajudaju A se awon Ibuso Irawo sinu sanma. A si se e ni oso fun awon ti yio ma wo o.
Eri leti inu Bibeli:
Isaiah 47:13: Are mu o nipa opolopo igbimo re. Je ki awon awoye-orun, awoye-irawo,
awon-afi-osupa so asotele, dide duro nisisiyi, ki nwon si gba o lowo nkan wonyi ti yoo ba o.
Ifihan(Revelation) 12:1
Ami nla kan si han li orun; obinrin kan ti a fi orun wo li aso, osupa si mbe labe ese re, ati ade
ONIRAWO MEJILA si mbe li ori re.
Orin Dafidi 8:3
Nigbati mo ro orun re, ise ika re, osupa ati irawo, ti iwo ti se ilana sile.
Gbinyanju lati ni iwe apakini iwe yi lowo, tia pe Akole re ni: Iwe eko imo ijinle nipa irawo eda "Taa
Ni Mi????". Tori o ko oun to po si nu, tosi ye kia mo kiato le ka ti Apakeji yi.
Gbinyanju lati ri wa ba asema soro boya lori ero aye lujara ni tabi lori ero alagbe ka, tori emi se tan
lati ma tan imole sinu aiye eda, Ki Olohun na si tan Imole sinu aiye mi, ameen.

3
ALAYE LORI PLANET TIA NLO
Gbinyaju lati ni apakini iwe yi lowo, ki apakeji yi le ye re dada, tori ibi ti apakini sun si ni apa keji yi
ti dide.
24/7
Kini itunmo 24/7 ninu ile aye yi?
24/7 je wakati iyipo ojo kan, niyi to je pe planet meje ni ndari aiye. Awon planet meje yi si nma
yipo aye ni igba merinlelogun gbogbo won si ni won ni wakati ti won nfi yipo.
Awon planet yi won a ma bere ise won ni dede awon ago wonyi: 6:30am, 6:33am, 6:35am, 6:40am,
6:45am, 6:50am, 6:55am, 7:00am, 7:05am. Gbinyanju lati ri mi ki fun e ni nkan ti wa fi ma mo
akoko ti won bo si, tie npe oruko re ni Planetry Time.

SUNDAY MONDAY TUESDAY WEDNESDAY THURSDAY FRIDAY SATURDAY


1 Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn
2 Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter
3 Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars
4 Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn Sun
5 Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus
6 Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury
7 Mars Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon
8 Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn
9 Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter
10 Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars
11 Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn Sun
12 Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus
13 Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury
14 Mars Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon
15 Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn
16 Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter
17 Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars
18 Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn Sun
19 Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus
20 Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury
21 Mars Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon
22 Sun Moon Mars Mercury Jupiter Venus Saturn
23 Venus Saturn Sun Moon Mars Mercury Jupiter
24 Mercury Jupiter Venus Saturn Sun Moon Mars

4
ALAYE LORI PLANET SUN
Ninu iwadi, a ri wipe planet orun je eyi to se ipase Agbara ati Idabo bo kuro nibi aburu.
Oun na lose afihan ikapa gbogbo aye wa ati emi wa.
A tun ma se apase lori gbogbo ero okan wa tabi kani oun na lo nse ijeni nipa lati ma se nkan, nipa
irori wa ati oye ti nbe lara wa, paapa julo yoo tun ma mu aseyori wa lori gbogbo oun taba dawole,
oun tun se ipase oro (wealth), orire okiki, oun latun ma se ikapa lori Bi eniyan yoo se ni imo lori
ogun lilo tabi sise, ati oyaya.
Ki wa ni oun ti Planet (Sun) Orun ma nse ikapa re ni wakati tie?
Ni wakati ti Planet Sun ba nse lowo, yoo ma bi awon nkan wonyi sile:
1. Okun ati Agbara
2. Aseyori
3. Ifokan sun
4. Ipase
5. Ero
6. Iwa imotara eni
7. Igboya
8. Irori
9. Wiwo eniyan san
10. Itoro Agbara
Ni wakati orun, wakati yi je wakati idunu ati aseyori gegebi a se ti so loke yi, aseroyi yoo si ma wa
nibi idawole lori gbogbo oun taba se, wakati yi na si je wakati tia le fi erongba wa han si enikeni tabi
si ounkoun eyiti yoo si ma di atewogba.
Orun je oun ti oni adamo bi ina, tia ba si fe se Ise tafe jo tabi ise kan toba ni ina ninu. Iru ise bayi yoo
ma dara ni jijo ni akoko ti Ipase Orun ba ndari ojo tire gege bia tise mo wipe Planet sun lo ndari
Sunday. Ise jijo yoo wa dara ni igbakugba ti Orun ba wa ninu irawo ina, fun apere, Sunday taba ti ri
Ninu gbogbo osu irawo ina meteta ni a ma lo ju.
Gbogbo Sunday inu osu irawo Aries
Gbogbo Sunday inu osu irawo Leo ati
Gbogbo Sunday ninu osu irawo Sagittarius.

ALAYE LORI PLANET MOON (OSUPA)


Ninu iwadi lori ipase ati Adamo ti osupa.
Iwadi fi yewa wipe Osupa je Olori (Queen) si Orun tori Orun je Oba (king) ni tire.
Obinrin ni osupa je nibi ipase tire.
Osupa nitire wase npase okan (mind), osi je eya kan ti ma para gbogbo irawo mejila tia ni larin osun
kan, gbigba inu irawo kankan koja sini oni oun ti ma nso ninu aye omo eda eniyan.
Planet Osupa wa je eya omi tori oun nikan ni ndari Irawo omi tia mo si Cancer idire tofi jepe akoko
ti Osupa ba gbinle dada bi igbati oba pe ojo kerinla, oru (heat) kii fibe mu ni akoko yi, beesini oru
(heat) ki mu ni oru.
Osupa je oun to se pataki ninu isemi awa eda, atiwipe oun na tun ni Agbara tire loto, oun sini planet
to yara ju ninu gbogbo planet tani, osupa tun je afihan ilera awa eda. Gbogbo oun ti nje omi ninu ara
awa omo eda Osupa ni nse ikapa re, latori ito, ito, ato, omi ara, omo oju.
Kiwa ni oun ti Osupa kosi inu, awon nkan wonyi lao ma ri ninu re:
1. Owo (Respect)

5
2. Orun (Sleep)
3. Idunu
4. Irin ajo
5. Omi
Wakati ti Osupa ba nsise lowo, oun na yoo ma je wakati toye kama se ise bi ise abo (security) ati ife,
ti wakati yi ba sise lowo, tia ba bere nkan lowo iyawa, obinrin kobinrin tabi iyawo wa yoo si ma je
itewo gba nitori Osupa je Eya Obinrin idire re tose nise pelu obinrin, akoko Osupa yi tun wa da lati
ma da oro ife sile larin iwo ati arabinrin re eyi ti yoo yori si rere bia ba se nfe besi ni ayi pada rere
yoo ma ba ife towa larin iwo ati ife re, sugbo akoko planet Venus lodara ju.
Fun iwo toun woju omo iba daara ko lekun ninu adua/ajo omo ninu wakati yi.
Gege bia tise mo wipe Osupa je ipase ojo Monday awa tia fe se ise kan tabi aajo kan tabi afe lo sise
lodo ni, tabi afe lo ri nkan mole leti odo ni. Ojo Monday lo fi ndara julo.
Tabi gbogbo ojo Monday tabi ri ninu irawo omi bi:
Gbogbo Monday to wa ninu Osu irawo Cancer
Gbogbo Monday to wa ninu osu irawo Scorpio
Gbogbo Monday to wa ninu irawo Pisces

ALAAYE LORI PLANET MARS


Planet Mars je planet eya planet okunrin tosi ni afihan awo pupa, pelu eya ina, osi je eyi to gbe. Ninu
afihan re miran tuni afihan agbara, o tun je planet ti nma da asasi pada, planet yi wa nise pelu oun
ti eniyan je bi afokan si ojo iwaju eni.
Ti Planet Mars ta nwi yi to ba ma jeri gbeyan ninu igbesi aye re, yoo bi awon nkan rere sinu aye
onitoun bi:
1. Oni toun yoo ni igboya,yoo si dara re loju lori gbogbo oun ti nba se.
2. Yoo ni ifarada lori ipokipo toba ba ara re.
3. Yoo ni agboye to peye
4. Yoo rorun fun lati le se ariyanjiyan
5. Yoo ni emi ilosiwaju lara
6. Yoo ni opolo pipe
7. Yoo tun ni okun (Strength) to dangajia.
8. Yoo ni emi lati ko awon eniyan jo lati je olori won.
9. Yoo ni emi aseyori lori gbogbo erongba re.
10. Yoo ni ipinu to daloju

Sugbon ti Planet yi ba jeri tako eniyan ninu isemi re awon nkan wonyi ni yoo ma han ninu iwuwa si
re ati aye re, iru enibe yoo ni awon nkan wonyi:
1. Yoo ma da nkan ru ni, ibikibi toba wo yoo ma daru ni, koda ki nkan ku bi iseju meji ko to daada ti
iru eniti planet mars yi bati tako kadara re ba dasi oro yen, gbogbo oro na yoo si daru lati oke dele.
2. Yoo je eniti yoo ma binu ni gbogbo igba, ti nkan kekere ba sele esekese ni yoo ti binu.
3. Yoo ni iwa tinu mi ni mase, koni ma gba imoran enikeni mo tire, oun toba ro ni abe ge, oun toba so
ni abe ge
4. Ibi ariwo leti ma ba iru eniyi ki nsi nibi ka to oro.
5. Yoo ni emi igbonara lara nipa ti ibalopo debi wipe yoo ma fe ma fi ipa bani lopo.
6. Koni ma ro oro ojo iwaju re

6
7. Ti planet yi bati tako kadara eyan, Aburo re lokunrin yoo jiya nkan yoo si le koko fun
8. Koni roju raye lati oko oro jo
9. Paripari re gbogbo property (Ogun) toba kojo gbogbo re ni yoo pare loju aye re nitori emi buruku
ti nba gbe ati itako ti planet yi je fun.
Gege bia tise so ni oke wipe afihan awo planet yi je Colour red iyen awo pupa, awo pupa yi sini oun
ti nse ninu isemi awa eda nigba tia ti bi omo na titi wo igba ti yoo wole. Fun alaayre:
Lakoko, ni igba ewe omo to ba nlo iru planet yi, wiwo aso alawo pupa yoo se idabo bo fun kuro nibi
arun, arun edo.
 Yoo ma bukun iwuwo (weight) omo na.k
 o ni jeki omo na le ma debi ina ti yoo wa fi jo.
 Koni jeki omo na le towo bo omi gbigbona tabi oun toba gbona
 Atiwipe yoo ma se alabo fun kuru nibi ina.

Elekeji nigba toba wa ni odo:


 Yoo ma yo kuro ninu ewu jamba oko
 Yoo ma yo kuro nibi jamba ina dida, bi igbati aba dana ounje lowo.
 Yoo ma se alabo fun nigbatoba nse nkan osu, koni jeki ko ma ri inira tabi inu rirun nigbati o
ba nse nkan osu.
 Koni jeko ma ri arun omu didun tabi inu rirun.
 Koni jeko ri ogun oyun sise
 Yoo ma yo kuro nibi ise abe nigbati o ba fe bimo.
 Yoo ma se ipase opolo pipe fun.
Awon nkan tia kasi oke yi yoo ma je fun omo na niwoba igbati o ba nwo aso pupa na.
Tia bati wa ni Wakati Planet Mars yi, yoo je akoko ti a gbodo ma wa tifura-tifura, eyiti asi gbodo jina
si gbogbo nkan to lee se wa lose, koda ti ipe ba wole ni akoko yi tifura-tifura lagbodo wa, alejo toba
wa ni akoko yi e fura si kie si sora.
Lotito la mo wipe Planet Mars ni nse ipase ojo Isegun tia mo si Tuesday, ti ojo yi si nje ojo ti Mars
yoo ma se Ipase iso ati abo, ojo yi wa dara lati se adua tabi aajo bi:
Adua isegun Ota
Awenu
Tude
Agbelepota
Aseta
Madarikan
Igboya
Owo (Respect)
Ikiya
Adua ibori ota.
Gbogbo oun tia kasi oke yi na dara tia ba le ma se tabi ma bere Adua re lojo Tuesday.
ALAAYE LORI PLANET MERCURY
Planet Mercury Je Planet kan to tayo larin awon planet tia ni, otun je planet alayipada ti ki nduro sibi
kan, otun je planet to ma nwa larin, ko ki n fi seyin beeni ko ki n fi siwaju, seyi se eyi so oun planet
ni.
Planet yi na lo ma nse ipase ero meji ninu aiye omo eda eniyan, ti planet yi bati bere ise ninu igbese

7
aiye omo eda eniyan, oun lo ma nfa ti awon elomiran fi ma ni Ero meji lori, fun apeere bi kin se eyi
tabi ki ma se eyi. oun lotun ma nfa ero meji towa ninu iwa awon omo onirawo Gemini ti won ma nfi
ni ero meji lara tabi awon omo tia bini ojo Wednesday.
Planet Mercury lo nse afihan iru lakaye ti Olohun damo eda ati iru isakoso imo ati ogbon ijinle ti yoo
wa lara omo eda.
Oun na lotun nse isakoso Ojogbon boya lokunrin tabi lobinrin.
Ti iru planet yi ba wa ninu isemi aye eiyan, yoo ni:
 Opolo pipe
 Opolo re yoo mu yanyan
 Yoo ni agboye daadaa debi wipe ki won to ko iru omo na ni nkan esekese ni yoo ti mo
 Yoo si tun ma ni iranti awon nkan toti se seyin.
Planet yi lotun se akoso bibi omo, tia ba wa ba planet mercury pade pelu planet Jupiter tabi Venus,
eyi yoo ma fi se afihan wipe, omo na yoo ni ero Oloselu lori, yoo dangajia nipa oro oloselu.
Planet yi lo ma nfa ti awon eniyan mi ma nfi se ito pinpin nkan, eko, oye, iwadi imo lori oun koun.
Koda ibiti agbara planet Mercury le de, eni toba ni lara ko nilo oluko kankan lati ko nipa imo kan ti
yoo fi mo, pelu imo ijinle, agbara re yoo tu ma se ipase Imo ikoko ninu aiye re.
Sugbon ti planet yi bati tako eniyan yoo ma ni awon iwa buburu lara bi:
 ko ma ko oun ti kodara abi so oro koro
 oro egbin
 Yoo ya opuro laye
 Yoo feran tete tita
 Yoo ni iwa ijora eni loju
 Yoo ma ro wipe oun loun gbonju
 Yoo ma fi oro gbe ara re ga
 Yoo si tun ma gbori yin fun ara re.
Ti planet yi ba tun fe fi iya jeyan;
Iru omo be yoo ma ni iru awon arun wonyi lara tabi kani Adamo:
 Oyi oju yoo ma ko awon omo yi
 Arunn opolo
 Iko ti yoo ma mu aya dun yan debi wipe aya re yoo ma ta
 Omo na yoo ma kilolo
 Ahan omo na yoo lo konile soro dada (oun lo ma nfa ta ma fi nri awon omo kan ti ahan won
ma fi nlo ti oro koni ja geere lenu won).
 Omo na yoo ma da ito lenu
 Omo na yoo ya arindin (Arun arindin; ma nwa lati inu opolo, arun opolo nani arindin je).
 Omo ika ese ati owo yoo ma dun iru omo be
 Yoo ni arun ete (adete). Tori planet yi lo n se akoso awo ara (skin)
 Ti iru omo na ba jeun, ounje na koni tete da ninu re.
Gbogbo awon nkan taka soke yi lao ma ri ninu planet mecury nigbati ba nsise.
Gege bia se ti gbo ninu eko tateyin wa wipe Ojo Wednesday ni mercury nse ipase re.
Wakati planet yi ma nise pelu:
Ofin, eko, o si dara pupo fun irin ajo. Ojo Wednesday yi tun dara fun ijiroro pelu molebi,
awon oniwosan yoo tun ma lo ojo yi lati fi ma se itoju alaisan.
Awon Adua/aajo won yi loba ojo yi mu bi:

8
Adua Imo/ Aajo imo
Isoye
Ohnmo
Gbalamo
Tabi lati wa idi imo ikoko.
Gbogbo Ise toba ti jemo onmo lodara lojo yi.

ALAAYE LORI PLANET JUPITER


Planet Jupiter yi je eya planet kan toni adamo ina lara. Oun lo nse ipase Ola (noble),orire, Omo bibi,
adamo okunrin, idunu, idagba soke, ireti, esi rere lara eda, oun na sini planet ti nfi aponle si ara omo
eniyan nigbati oba wa ninu isemi eniyan.
Awon omo ti planet yi ba wa koja ninu isemi won ni akoko tia bi won, iru awon bee la ma ri ti won
ma ni inuunre ati iwa otito. Planet Jupiter yoo ma se ipase irori jinjinle, idajo to peye, eko, esin,
ifowo pamo, Ojogbon, ati bia se n gbe ero lori owo nina, (ekunrere oro yi nbe lara awon omo tia bi ni
Ojo Thursday, niyi to wa ni abala oju iwe 66 ninu iwe (Iwe Eko Imo Ijinle Nipa Irawo Eda (Taa Ni
Mi ????) E lo ka nibe fun agboye lori awon omo Tia bi ni Ojo Thursday kie si wo iru nkan ti Jupiter
bi si awon omo Thursday lara.
Ti Planet Jupiter yi ba ma gbe eniyan yoo ma ni awon nkan wonyi lara:
 Yoo ni oye pupo lori
 Yoo ni inu rere, oun rere ni yoo ma se
 Aye iru omo be yoo kun fun ayo
 Yoo ni Oro/Olowo
 Yoo ri omo bi
 Yoo ma ri agbega ni aye re
 Yoo je Ojogbon
 Yoo je eniti yoo ma ran omolakeji re lowo.
 Yoo ma ni akojo rere
 Yoo ma wa nibi irorun ki yoo sini ibi jagidijagan
 Yoo ni ilera to peye.
Sugbon ti Planet Jupitet bati tako kadara eyan tabi ki Planet yi ba wa ni ipo aidara nigbati o ba nbe
ninu irawo kan, nitori oni iru irawo to ma wa koto le jeri gbeyan tabi tako eniyan.
Iru awon nkan bayi lao ma ri ninu aye omo ti Jupiter tako irawo re:
 Ki yoo ni iwa iwontunwonsi lara bi ki nkan aburu ma sele ni yoo ma wu
 Yoo ni iwa ikoja-aye
 Nkan koni dan fun Omo na
 Gbogbo agbonkanle iru omo be yoo ma jasi asan.
 Ki yoo ni amojuto nkan rara
 Yoo ma je gbese kakiri ni, kosi iru iranlowo tole wole fun, gbese ni yoo ma fi gbogbo ojo
aye re je
 Gbogbo oro re koni wo, bee toba dasi eto kan tabi nkankan ki yoo ri eso rere nibe.
 Gbogbo ero re yoo ma kuna.
 Yoo ni idamu lori omo bibi tabi ki awon omo re je irinse ibanuje fun.
 Ki yoo ni iwa rere lara
 Ti iru omo bayi ba nreti ire lati owo enikan kiyoo bo si fun (niyi toun tunmosi ijakule)

9
 Okiki iru omo bayi ma nkere pupo
 Yoo ma ri idina ore
 Ki yoo mo ejo da rara.
Ni akoko ti Planet Jupiter yi ba nsise lowo, Wakati yi yoo je wakati ti a le se alekun si ibere wa, to si
je wakati ise konge oore eyiti ao ri oore ofe ati aanu lori idawo lee wa, Wakati yi dara lati beere nkan
lowo eniti a fe gba nkan lowo re, eyi ti yoo si fun wa ni alakun si ibere wa, gbogbo ohun toba sele ni
wakati yi oore ni yoo jasi ni igbeyin.
Gege bia tise mo wipe Planet Jupiter ni ndari Ojo Thursday, ojo yi si je ojo ti Alubarika kun inu re,
ojo yi si je ojo ti a lee se adua lati fi toro Ohunrere lodo Olohun taosi ri iyori adua na si ibi rere ni
kiakia.
Awon adua tabi aajo wonyi lodara lati se ni Ojo Thursday:
 Adua Oja tita/ Awure Oja tita.
 Adua Arisiki nla/ Awure Okiki nla (Tao fi di eniyan pataki lawujo tabi eniti aye nfe).
 Adua siso ota meji di ore/ Tabi iferan larin iyawo meji (fun iwo toba fe iyawo meji ojo yi lo
dara ju lati se iferan si arin awon mejeji).

ALAYE LORI PLANET VENUS


Planet Venus je planet tia le pe ni Orisa ife, igbayawo, ewa ati itunu, nitori oun lo mu okun emi awon
nkan wonyi dani. Planet Venus je eya Obinrin, ni yi ti planet yi nse ipase irawo Taurus ati Libra.
Gege Bia ti se wa so wipe planet yi je planet eya obinrin oun lo fi mu planet yi je planet to ni iwa
irele, iwa isonidotun.
Tia bawa woye si awon ti won nlo irawo ti planet yi tabi ti planet yi ba koja ninu kadara tosi jeri gbe
won, iru omo be yoo ni iwa to dara won yoo si tun ni iwa oyaya.
(Ekunrere oro yi nbe lara awon omo tia bi ni ojo Friday, niyi to wa ni oju iwe 66 ninu Iwe Eko Imo
Ijinle Nipa Irawo Eda Taa ni mi ????) E lo ka nibe fun agboye lori awon omo tia bi lojo na, kie si wo
iru nkan ti Venus bi si ara awon omo Friday.
Gege bia tise mo wipe planet Venus lo nse ipase ojo Friday atiwipe ti planet yi se wa je Planet ife,
akoko tabi ojo ti planet yi ba ndari, o dara lati ma se adua iferan tabi lati fi se adua tia ma fi sunmo
Olohun dada tao si di ayanfe Olohun pelu.
Gege bia tise so wipe, Planet/ojo ti planet yi ndari tia mo si Friday yi dara fun Ewa tabi ise araloge ,
fun apeere:
Irun gige, irun sise loge, ise ara tabi awo loge, ile kikun, ati pe gbogboun tia ba se fun Ololufe wa ni
ojo yi koni burewa sugbon yoo maa rewa sii ni lojojumo.
Uhmmmm. Opo eniyan ni komo pe ojo Friday ti venus ndari re yi lo dara ju fun igbeyawo tori Venus
lagbara ninu iriajo igbeyawo.
Awon Adua/Aajo wonyi lo dara ju ni Ojo Friday ni sise:
 Adua/Aajo iferan
 Ki Olohun tubo fi yewa ju bayi lo.

ALAYE LORI PLANET SATURN


Planet Saturn je planet ti nse adari emi gigun. Agan planet si ni , o ma se akojo nkan, oun na ndari
otutu, idaabobo, otun je planet Aifarabale, pelu pelu re, oun nikan loje planet to je Planet Alasiri.
Ti planet yi bawa ninu irawo ti venus ndari re bi irawo:
Taurus irawo Erupe

10
Libra Irawo Afefe
Omo tia ba bini akoko yi Planet Saturn yi yoo je Ajile (fertilizer) fun kadara omo na, yoo se orire
laye re lati ibere pepe aiye re kosi ni ri iponju. Amo ti planet yi saturn bawa ninu irawo ti planet
mercury ndari re bi:
Gemini irawo afefe
Virgo irawo erupe
Planet venus yi koni jeri gbe, yoo si ni ifaseyin ni aye re, nkan yoo le koko fun, yoo si ri idina.
Gege bi eya ti planet yi je, awon nkan wonyi lo ko dani:
 O ma nfa idaduro sinu aye omo eda
 O ma nfa adunrun mo sinu aye omo eda
 O ma nfa ijakule sinu aiye eda
 O ma nfa idaduro iro-idunu sinu aiye eda
 O ma nfa idina ireti ore sinu aye eda
 O ma nfa ikoro sinu aye eda
Ni kukuru gbogbo oun toba ti je aburu lati odo planet Saturn yi loti wa.
Sugbon botun se wa je planet aburu to otun ni oun ti nse gege bi ise miran bi :
 Idaduro nibi ise.
 Itoju
 Ise suuru lenu ise
 Ijora eniloju
 Ima toju asiri pamo
 Amumora
 Iso nipa owo nina
 Iduru sinsin
 Ima kora eni ni ijanu
Iteseiwaju Oro yi nbe ninu Iwe Eko Imo Ijinle Nipa Irawo Eda, Taa Ni Mi ????, ni abala iwe na lao
ti ma ba iru awon nkan ti yoo ma sele si awon omo tia bi ni Saturday.
Ni akoko ti planet yi ba nsise lowo, ti nkan kekere ba sele o le di ariwo, eyiti agbara ko nile ka mo,
eyi sile fa ikabamo ni ikeyin, kia sora fun akoko yi tori awon ariyanjiyan ti yoo fe ma sele. Fun Adua
tabi Aajo:
 Adua emi gigun
 Gbogbo ise to ba ti nba afefe sise lo dara lati se ni ojo yi bi: Ase, Olugbohun ati beebe lo
ALAAYE LORI PLANET RAHU ATI KETU
Awon Planet meji kan nbe tia mo si Rahu ati Ketu, awon planet meji yi je planet ti kofi ara han ni oju
orun pelu aworan kankan loju orun, a ma npe won ni Planet Ojiji.
Awon planet meji won yi, won kose gbe ara le gege bi awon planet yoo kun bi, Sun, Moon, Mars,
Mercury ati beebelo. Nigbakugba ti planet yi ba nsise, won ma ko eyin si awon irawo mejila tia ni.
Adamo awon planet yi je afihan aburu ni kukuru ise aburu ni won ma gbe kiri gege bi Planet Saturn
na se ma nse, amo ti Awon planet yi bawa pelu planet miran ninu ile kan tabi tiwon ba pade ninu
irawo kan tabi ile kan osese ki won se ipese rere, fun apere ti Planet Rahu ati Planet Sun ba pade
papo ninu ile kan tabi irawo ipade awon mejeji yi le fa ki won dijo se ise rere.
Lotito adamo awon planet yi, adamo aburu ni won gbe dani, sugbon Planet Sun ati Mars kofibe ni
ise aburu pupo bi ti won to kun, koda awon eyi tia so wipe won buru, ti won ba de aye kan ise rere ni
won yoo se fun eniyan, fun apere tia ba lo wo inu iwe owo wa tie ba wo oro tia kosi abe planet saturn

11
e ma ri wipe nkan aburu po gidigidi labe re, koda o ma nle gidigan fun awon omo tia bi ni Saturday
lati se orire, bi ewuro ni oro won si ri, tori toba pe toba ya, ire no yoo gbeyin isoro won, won yoo ni
emi gigun, bee na lose ri lodo Rahu ati ketu na, amo oo ti won ba ri Planet gidi pade tabi ti won ba
bara won ninu ile irawo kan, won yoo pa ise aburu won ti, won yoo gbe ise rere dani, Jupiter nikan lo
le dari Rahu ati Ketu, ti awon mejeji yi yoo si gboro si Jupiter lenu.
Ninu gbogbo planet mesan tia ni, Meri dara marun ko dara.
Eyi to dara ninu won re:
 Moon
 Mercury
 Venus
 Jupiter
Won yi ni awon planet marun ti ko dara:
 Sun
 Mars
 Saturn
 Rahu
 Ketu

12
ITESIWAJU LORI AWON IRAWO MEJILA TIA NI
ITESIWAJU LORI ORO AWON OMO ARIES ATI BIA SELE BA WON GBE:
Gege bia tise mo wipe awon omo yi je:
Onigboya, Won si ma mu ipinu won wasi imuse lori gbogbo ibi ti won ba gbe ero okan won si.
Igboya won dangajia, won si tun ni igbona okan, won je eda kan ti won ma ni ireti, won si tun ma
duro nini lori oro won, oro won ki nyi pada. Won si tun ni emi itara lara. Leyin awon oro tia ka si oke
yi, won tun wa ni idakeji re ti nse Aleebu won.
Wonyi ni Aleebu ti nbe lara awon omo yi:
Won je Omo Alaini suru rara, won ma dinu, won si je oni binu ti nma binu pupo. Won si tun ma nwu
awon iwa airotele.
Leyin igbati ati ri awon oro won yi tan, awon na ni oun ti won feran ati oun ti won ko feran.
Oro lori oun ti won feran: Won feran aso wiwo to ma n mu ewa won han sita, won si feran ki won ma
wa nipo Olori tabi ki won fi won si ipo olori ni ayekaye ti won ba wa, won si tun feran ere idaraya.
Amo nkan won yi ni won ko feran lati ma se tabi lati ri: won korira ki eniyan ma se imele, beeni won
korira idaduro, atiwipe ise tiko bati jo mo ona won tabi ti ise yen ko ba ebun ti Olohun fun won mu,
inu won ki ndun si rara.
Awon omo yi je omo ti won ma ni eyin wewe ni erigi isale won, ni oke erigi won eyin nlala lo ma
nwu nibe, nigbamiran, eyin kan ninu eyin iwaju won ma nta gangan sita tojasipe, eyin kan ma gun ju
ti awon miran re lo. Ti awon omo ti ba nbinu lowo oju won ni won ma nsaba gbe si ju, to si jasi pe
oju won ma nkoro ti ibinu ba wo won lewu tan. Eyi ti Olohun ba fun ni anfani lati kuro ni ilukan losi
ibomiran, irinajo na ma nje irin-ajo Olojo gbooro, papajulo ninu isemi won, won a si tun mo lo irin
ajo loorekoore.
Won ma ni isese lori won, tabi oju egbo toti jina. Aisan bi iba ma nse won, koda won a si tun ma ni
aisan eje. Eyinju won ma ntobi die niwonba, beesi irun ori won ki nsaba kari ori won. Won ki nsaba
bi omo pupo, won si feran ounje.
Larin awon odun wonyi ki nsaba si anfani rere fun won nibe:
1, 3, 6, 8, 15, 21, 36, 40, 45, 56, 63
Sugbon larin awon odun yi oun rere ma saba sele si won tabi kani anfani rere nbe fun won larin
awon odun na : 16, 20, 28, 34, 41, 48, 51

ALAAYE LORI BIA SELE BA OMO OKUNRIN TI NLO IRAWO (INA) ARIES GBE
Ominira ni kokoro to so irawo awon omo Aries ko, gege bi ideda won ti se je eda kan ti ki ngba ki
won pase fun oun ayafi ko jewipe oun ni yoo p'ase na.
Eyi ni ona ti obinrin/okunrin le gba lati jere ife okan awon omo aries tabi lati jeki ife won lekun si
lemi won, lakoko, okunrin/obinrin to ba fe ba okunrin aries gbe papo gbodo je eniti yoo ma tele ofin
re gege bi iwa adamo tia dasi ara awon omo na. Lotito ni wipe, ideda awon omo yi je ideda ti nma
bori isokisoro toba daju ko, tabi kani Olusegun ni won, won ma ri opolopo isegun lori isorokisoro ti
won ba daju ko, idi ti oro yi fi ribe nipe, planet ti ndari irawo omo yi je Planet Mars niyi ti alaye
gbewa wipe, planet yi ni apase ojo Tuesday, niyi ti itunmo gbe wa ninu ede yoruba pe Tuesday je ojo
Isegun idiniyi ti awon omo yi fi je Olusegun lori gbogbo oun ti won ba da oju ko. Awon okunrin won
ma ni erongba lori oun ti owo won kole to, won a ma ni ireti lori nkan ti kole te won lowo, fun idi eyi
okunrin/obinrin to ba fe ba Omo aries okunrin gbe lai ni ja tabi laini si gbonmi si omi o to,
okunrin/obinrin na kogbodo re ara re sile, okunrin/obinrin na gbodo gbe ara re si ipo giga, ipinu yi lo
ma wu omo aries lori, tori gbogbo ero okan omo okunrin aries na yoo wa da lori bi yoo se je oga le

13
lori.
Lotito Awon okunrin aries ni iwa ifigagbaga, fun idi eyi okunrin/obinrin toba fe ba won gbe, gbodo
ma fi ye awon omo na wipe won kole bori oun. Amo lekankan a gbodo ma fun awon omo na laye
lati ma je oludabobo lori wa, tori won feran ki eniyan gbe won si ipo oludaabobo.
Ti ija ba sele larin iwo ati omo Aries Okunrin, mase beru lati pariwo mo pada, tori tio ba tiri wipe
oun pariwo mo e, ti iwo na o wa da pada, esekese ni yoo ti so ireti nu lorie.
Awon alebu kankan tao tun ma ba pade lara won re bi: Afemi-Afemi, Iwa igberaga, Olokanlile,
sibesibe won laya, idawole rere ati iwa itara.
Ibasepo larin awon omo Onirawo Aries lokunrin kun fun igbadun ati idunu, sugbon o le ja ololufe re
kule tabi ko ko eyin obinrin na si orun ale iyen ti Obinrin to je Ololufe re ti ko ba tele iwa to wa ninu
Omo Aries.
ALAAYE LORI IBAGBOPO FUN OBINRIN ONIRAWO ARIES
Awon Obinrin onirawo Aries je eni ti ko ni iberu enikeni lokan, awon na si je Olori rere.
Won je eda kan to ni okun pupo, ara won dabi emu (Eniyan yoo ma feran won) beena awon na feran
ifigagbaga gege bi okunrin won ti ma nse.
Tia ba wa ri eni to fe fe awon omo yi, ki okunrin na farabale dada fun obinrin na lati denu ife ko won,
tori awon obinrin won ni isesi "Fun rara okere ni fi enu ara re pe olode" to ba ti wa se bayi tan, eyi to
kun ni wipe ki okunrin na wa so ero kan re fun.
Awon obinrin ti won bi si abe irawo yi ni emi itara fun Ibalopo, tabi kani won kundun ibalopo, eyi lo
fa ti won ki nfi tako awon okunrin. Won ki se imele rara lorekore lara won ma nya gaga beeni won ki
nfe gba ki okunrin je oga lewon lori.
Lotito obinrin won nifesi lati ma fi ife han, amo won a si tun fe ma wa ni ipo olori. Lafikun awon
obinrin yi ki nfe ki eniyan ko enu si won ayafi eniti won ba nife si.
Eni toba gbe aries obinrin sile gege bi iyawo, yoo ni lati fun obinrin yi laye lati ma mu oro wa lori
erongba oko re. Ti okunrin na bati nse eyi, obinrin ti nbe labe irawo yi yoo nife re gidigidi, ife re yoo
si je ife otito niyi ti koni se oju meji, amo obinrin na je Ojowu. Irin ajo ife pelu awon obinrin yi won
ma ngba akoko ati akiyesi to peye si gbogbo isesi re, nitori won feran ki ololufe won ma fun won ni
aye lati ma bawon jiroro.ibalopo je aye ti awon obinrin won ti ma se aseyege ati ifarakanra.
Ete (lips) ni ewa won ma saba wa, ete won ni maa saaba fa oju okunrin mora.

ITESIWAJU LORI ORO OMO TAURUS ATI BIA SELE BA WON GBE
Gege bi ideda awon omo yi se je ti won ni awon adamo yi lara:
Awon omo yi se gbekele, onigbekele ni won, beeni won si se gbara le pelu tori won ki nsaaba da ore
won, won tu je eda kan to ni suru lopolopo lori oun ti won ba nse (sugbon ti eniyan ba se won, ni
asiko yi inu ma nbi won gidigidi gan ni). Won ni emi in ifokantan (ki eniyan fi tokantokan se nkan
tabi ki eniyan fi gbogbo emi re sidi nkan) eyi lo fa ti okan fi ma ndoro sinsin lori oun ti won ba ni
lokan.
Wonyi wani Aleebu:
Hmmmm, gege bia tise so wipe awon omo yi je Onisuru to bee nani won se je ni Olokanlile, awon
omo yi shoro lati yi okan kuro nibi kan tabi lati seri won kuro nibi ero kan tabi ise, ninu iwadi, won
fi ye wa wipe ami idayato awon omo yi je ti (Titele) ni yi ti itunmore fi ye wa wipe eni toba ni iru
Ami idayato yi lara enina yoo shoro lati yi okan re pada.
Awon nkan wonyi ni awon omo yi feran lati ma se tabi lati ma ri, bi:
Ki won ma ko awon eniyan jo, tabi ki won saba ma wa ni ogba-ajara, papa julo won nife si ki won

14
ma wa ni owujo ti eniyan ba posi ju. Won feran ki won ma se ounje, beena sini won feran orin ni
kiko tabi ni gbigbo (ti iru awon omo yi ba wa ni ipo ibinu lowo e sa ti ma korin fun won tabi ki eto
ero igboun si afefe fun lati ma gbo, eyi yoo ma di ibinu won ku. Hmm won feran ifakora (Romance)
(Elo wo inu iwe eko imo ijinle nipa irawo eda lati ri ojulowo alaye yi nibe tori oro po nibe. Won si
tun nife si lati ma wo aso tabi ra aso olowo iyebiye.
Sugbon oooo, awon nkan wonyi ni won ko feran rara, bi:
Iyipada Ojiji tabi lati ma kuro nibikan bo si ibi kan, ninu imo ijinle irawo eyi lofi je wipe awon ti
won wa ni abe irawo yi ati awon omo onirawo Gemini kodara fun won lati bara won gbe papo bi
tokotaya, tori ideda awon omo Gemini je eya ti nlo Ami Idayato ti Elemi meji (seyi ma seyi), elero
meji ni won, ti won ba dijo gbe papo ituka yoo waye ni arin won latara Ami Idayato won, yato si
wipe irawo won ko baramu.
Won korira inira, ti inira die ba file kan, won yoo banuje pupo.
Lotito lo wa ninu adamo awon omo yi wipe won ma binu, sugbon ibinu won leekookan ni won ma
nbinu, ti won ba si binu tan won kin ko oun ti yoo ti eyin re yo.
Beenani leekookan ni won ma wa imoran lo si odo elomiran. Won gbadun iferan gan. Won si tun je
eniyan ti ma yan ore (friends). Gbogbo oun ti awon omo yi ba se daradara ni won ma nse pelu
igboya sini.
Won nife si awon oso ara tabi kani won feran lati ma se ara l'oge.Won ni iwa ito-sona bee na sini iwa
amumora.
Awon omo yi je eda kan ti ma gboro si awon obi lenu. Won je edakan ti ma lowo lowo won si ma wa
ni ipo aatata, sugbon oseesee ki won ri iponju nigbati won ba sese ndagba soke amo bi ojo base ngun
ori ojo iyipada rere yoo ma de ba won. Won ni igbagbo ninu Esin (Religion).
Otutu ati iko tun wa lara awon aisan ti ma saaba se won sugbon leekookan ni won ma nsaaba se
aisan.
Awon odun won yi je odun ti nkan le le koko die fun won: 1, 3, 6, 8, 33, 44, 52, 61.
Ki won sora lati ma dawole nkan ni awon akoko yi.
Awon odun won yi si je Odun to dara ju fun won lati ri ore gba tabi lati dawo oun rere: 2, 10, 16, 18,
20, 22, 36, 40, 56.

ALAAYE LORI BIA SELE BA OMO OKUNRIN TI NLO IRAWO (ERUPE) TAURUS GBE
Iwo obinrin to ba nwa Okunrin to lagbara, to je Olotito eda, enitose gbe okan le tabi tose gbe ara le
paapajulo iwo obinrin to nba wa okunrin Oninurere, awon okunrin tia bi si abe irawo yi je okan lara
won.
Awon okunrin onirawo yi je eni tose fi okan tan, tose gbe ara le, tosi tun je onisuru, amo ibi ti awon
na kun si ni iwa agidi inu won.
Ti obinrin ba nse bi eni ntasi okunrin taurus lona ti yoo fi gba tire tabi lati fi ife han, hmmmm, osese
ki awon okunrin yi ma wobe, tori won ko ni kobi ara si gbogbo asehan obinrin na, tori won je eda
kan ti ki ntete gbo agboye si iru awon asehan be, amo ti iru obinrin be ba fe je ki okunrin taurus gbo
agboye oun ti nso, awon onimo ijinle irawo ni ki obinrin na fi enu ara re so oun to nfe gangan, tori
eyi yoo tete ye okunrin na ju ki obinrin ma fi oju soro fun lo.
Awon okunrin ti nbe labe irawo yi je eda kan ti ko nife si oun atawoda tabi afi itanje se, fun idi eyi
obinrin kobinrin toba fe ba awon okunrin yi gbepo gbudo je eniti ki nparo beesini gbogbo oro toba fe
ba okunrin na so gbodo je oro ijinle ti ko ni si aiyederu oro nibe. Ki Ololufe okunrin onirawo Taurus
(iyawo re) gbaradi lati ma fi gbogbo akoko re fi ife han si lati le jere okan okunrin Taurus lokunrin.

15
Lotito won je okunrin ti ma ntete gbo agboye oro, awon ni won ma npe ni (Abo oro to fun
Omoluabi), bee na sini won ki feran lati so oro pupo, eyi le mu ki ololufe re lobinrin ro wipe ko ko
ibi ara si ero oun, sugbon oo koribe gbogbo re loti gboye tori oro die to fun omoluabi.
Tia ba nso nipa awon okunrin onirawo to mo ina ounje gbo, okunrin Taurus je okan ninu won, tori
won feran ounje gbigbo, won si mo ounje se dada tori eyi je oun ti won feran, fun idi eyi, obinrin to
ba fe fe okunrin onirawo yi gbodo je obinrin to mo ounje gbo dada koda orisirisi ounje ni obinrin na
gbodo lo ko bi won se nse. Tori won feran ounje, ti obinrin bafe jeki ife re gbinle dada si okan Taurus
lokunrin hmmmmmm, ki obinrin na wa ile ounje to dara ju tabi ko ma gbo ounje aladindun si lenu,
Mofi Olohun bura ogun iferan tijina lati ma sa si okunrin taurus ni yen, koni wo ita mo niwonba igba
ti o ba nfi ounje de mo le, koni wo ita mo.
Won si tun feran ibalopo dada tori ibalopo dabi igbadun aiye loju won ni ati gege bi iwa eda.
Lotito ooo Olotito ni won, beesini won ki n da eda egbe won.
Sibesibe, ti obinrin ba file da won, o pari ni yen ooo, koni dari jin obinrin na.
Nipari, oro kan pere lo wiwo lenu awon okunrin taurus yi lati so fun obinrin ni "Mo ni fe re (I Love
You)". Oro yi wiwo pupo lenu won lati so fun obinrin.

ALAAYE LORI IBAGBEPO FUN OBINRIN ONIRAWO TAURUS


Awon obinrin won feran ki oko won ma fi ife han lorekoore si won.
Iwa awon omo yi je eyi ti ororun ju lati mo, gege bia tia se so lojo si wipe, won se gbe ara le, won si
je olotito ati bebelo. Bee nani awon alebu won se je eyiti ati menu ba tele ri sugbon lafikun, awon
obinrin won ya ole (lazy), awon na ni agidi okan pipo ju, won ni agidi debi wipe, won ki ngba boro,
amo tia bati se iru akiyesi bayi, ema ni lati fi ye wipe oun to se kodara to, kie si ma so fun wipe ko
ma binu, yoo tete ro lara re.
Nipa ti ife, won ma nda bobo ife won, bee sini won ki kuro nibikan bosi ibomiran, tabi kia ma pin ife
kaakiri, ife won ma nduro si ibi kan. Awon omo yi, ni eyinju nla, eyin ju won ma ntobi.
Bi eyinju won se wa to tobi yi, hmmm ewa lo kun nibe.
Kosi okunrin na to ma wo eyinju awon omo yi ti ko ni fe denu ife ko won.
Inu eyinju won ni gbogbo ewa won pari si.
Awon la n peni, ari male lo, Eleyinju ege, ti eyinju re nse wami wami.
Beena si lori lodo okunrin won na, walahi ti obinrin koba sora toba wo eyinju okunrin ti nbe labe
irawo fun iseju meta laiseju, hmmmmmmm, obinrin na koni le mu ada duro mo.
Erora wo eyinju won. Ninu gbogbo irawo, won je irawo to ma ntete jeun omo, ti won si ma ntete je
ere ise owo won.
ITESIWAJU LORI ORO AWON OMO GEMINI ATI BIA SELE BA WON GBE
Gege bi ideda awon omo yi se je ti won ni awon adamo yi lara:
Awon omo yi je oniwapele, bi ife bi ife lo ma nse awon omo yi, ero ife lo ma wasi okan won. Amo
awon omo yi won ki ni itelorun nkan. Olohun si yanda ifarada nkan fun won, ni ipokipo ti won ba ba
ara won, won ma n farada nani nitori won yoo ma ni ireti lati wipe oun gbogbo si n bowa da. Won si
tun je eda kan ti ma ntete ni agboye nkan tabi agboye ise, ayafi eyi ti koba wu won lati mo lokun,
kosi nkan ti won fe ko tabi ti won fe mo ti Olohun ki yonda re fun won lati mo, ayafi ti koba wa lati
okan won lati mo lokun. Eyi lo mu mi so ninu iwe akoko tia pe akole re ni "Iwe Eko Imo Ijinle Nipa
Irawo eda, Taa ni mi ????" wipe awon omo yi soro lati toju imo pamo fun tori toba ya, won yoo pada
ni imo yi.
Gege bi oro awa eda wase ri wipe a ki nle rin ki ori ma mi, eyi lao fi mu enu ba alebu won.

16
Alebu awon omo yi ni wipe: won ki farabale, bee sini won ki nse dede, bee sini won ki ndara won
loju lori ipinu won, eyi lofa to je wipe ti won bati gbero nkan lokan won, won ki ni emi idaniloju pe
awon yoo mu se, tabi ki won ma reti nkan, ero idakeji ni won yoo ma nisi oun ti won nro na wipe
kole wasi imuse.
Lara awon nkan ti won ma feran tabi kani to ma nmu inu won dun ni wipe: won feran orin, won
feran iwe kika, beeni won ma feran lati ma ka awon akosile, won si tun feran ijiroro ni awujo ti won
ba wa, ati nipa ka ma lo irin-ajo, amo irin-ajo ti won ki nse ti olojo pipe, bi kama kuro ni agbole kan
bo si omiran tabi larin ilu s'ilu.
Kiyesi; Awon nkan won yi ni won korira re, ti won si ki n fe ko sele siwon, bi:
Won korira ki won ma dawa lairi eni basoro, beesini isoro loje fun won lati wa ninu ahaman.
Awon omo ti nbe labe irawo yi, ki saba lomi lara, won ga, awo ara won si je eyi ti ko dudu ju beesini
ko pupo ju ayafi eyi to ba bora ninu won, felefele ni irun ori won.
Oro tutu loma jade lenu awon omo yi: ati so ninu iwe akoko wipe inu yara keta ni irawo awon omo
yi wa eyi ni oro siso kofi je isoro fun, amo awon okunrin to wa labe irawo yi, won gbona nipa kama
fi oro enu taniyanje, papa julo ti won ba nba obinrin soro ife, ti obinrin koba sora fun oro tutu enu
won, won yoo ma yofe ni, eyi losi ma nfa tojo wipe gbogbo igba ni won a fa ma gbo oro enu won
niyi ti yoo ma je ki ife won ko ma peleke si (Inu ohun enu won ni ewa won wa). Won je eda kan ti ki
soro tan, abo-oro ni won ma saaba so, eyi toba gbo ijinle yoruba ninu won, yoo ma lo owe tabi
akanlo ede nigbati o ba nsoro.
Ti awon omo yi ba n rin, ese won ma nya nibi irin, won feran iyapa, itunmo re ni wipe won ki nduro
lori ero kan, won tun je eni toni iwoye ikan, ki won to soro won a ti woye si, ibiti won ti bere oro na
ati ibiti oro na yoo yoju si, idi niyi ti won fi soro lati bori won nigbati won ba dijo nse ariyanjiyan
pelu eniyan tori tinu tita oro na ni won yoo ti woye si ki won to soro.
Lotito awon omo yi ma nbinu sugbon ibinu won ki npe rara ki won to ronu piwada, ibinu won ki nse
olojo pipe. Awon omo yi le sise laini simi tabi lai duro tori, ki n saaba tete re won, amo ki won sora,
tori eleyi le se akoba fun ilera won, tori toba ya ara yoo bere. Won je eda kan ti won ma ri anu gba
lati odo ore won tabi lati odo molebi won. Elebi pupo ni won (Large families). Tori kosi aridaju wipe
okunrin won yoo ni iyawo eyokan.
Ki won sora larin awon odun yi lati dawo le nkan tabi lati gbero nkan, tori ni awon akoko yi nkan ma
nfe le fun won: 1, 3, 6, 8, 33, 44, 52, 61.
Larin awon odun yi odara lati dawo le nkan tabi lati gbero nkan, beesini ni ki won gbinyaju lati de
nkan mole tori ojo waju won nitori opolopo ore ni nbe larin awon odun yi: 2, 10, 16, 18, 20, 22, 36,
40, 56.

ALAAYE LORI BIA SELE BA IRAWO AWON GEMINI LOKUNRIN GBE


Igbese aiye okunrin Gemini je eyi to kun fun idunu ati igbadun aiye, ayafi eyi to ba wa ninu odun ti
ko dara fun, ti eniyan ba wa pelu okunrin Gemini ti won dijo n ji roro oro, eni na koni mo ala wipe
oun wa ninu isoro kan, koda ti isoro ba n be lokan enina to ba file de odo awon omo Gemini yi, oro
na yoo fuye lokan re tori awon oro idinu ti yoo ma ti enu omo Gemini jade. Won je eni to ma ni
idawole lokan ti won si je alawada eda.
Gege bi adamo awon onirawo yi, okunrin won feran oro siso, won si je okunrin ti ma ngbe ife
obinrin sokan pupo ju, obinrin to ba fe fi ife han si awon okunrin ti nbe ni abe irawo yi, ko gbodo je
nibi ti ero po si bi ka ni awoju ero, o gbodo je oun nikan pelu obinrin na, idi ni wipe awon okunrin
towa ni abe irawo yi je adufe fun gbogbo eda, awon eniyan ma nfe ki awon ma wa pelu awon

17
okunrin ti nbe labe irawo yi tori oro ti won ma ngbo lenu won ati oro iyanju ti ma n jade lenu won,
tori re lofi je pe o ma fe nira die lati ri won basoro lawujo, ayafi ki won jo wa papo loun nikan
Gemini nikan.
Nkan eyokan to buruju nipa awon Gemini lokunrin ni wipe, won ko ni emi idara-eni-loju lori
erongba won.
E ma gbagbe pe ati so ninu eko isaju wipe awon okunrin Gemini je elemi meji, seyi-sohun, fun idi
eyi obinrin toba fe won iwa yi kogbodo je ajoji fun won, bee si nani iwa aisedede odo awon omo yi
lo wa, bi won se wa je eda to ni iwa aisedede to hmmm won ja fafa won ko gba gbere rara, iyalenu
lowa je wipe iwa ti nbe lara won yi lo ma mu ife won gbinle lokan obinrin.
Lodo awon onimo ijinle nipa irawo eda, won fi enu ko wipe awon okunrin abe irawo yi je eda kan ti
won ko se gbe okan le rara, bee sini ebi awon omo yi ko, nitori oni nkankan ti ma npa ase fun won idi
re re lo fi je wipe ti won ba ni ero nkan lokan wipe awon fe se, lojiji ti kini yi bati de siwon, won yoo
yi okan pada na lori nkan na ni esekese, idi ni yen ti won fi soro lati gbe ara le. Amo tia ba wa ri
obinrin to fe ba won gbe pe fun ojo pipe yoo ni lati lo ogbon orire, obinrin na si gbodo lo ko bi won
se nlo ero meji.
Ni opolopo igba ti okunrin toun nbe labe irawo yi bati soro efe (funny words) kan, gbinyanju lati fi
erin pade oro efe re, inu re yoo ma dun si ni, nipari obinrin to ba fe won, o gbodo ma gbinyanju awon
nkan tuntun lori ibunsun orisirisi ara (style) ni ko ma da fun o damiloju ko ni le wo ita mo.
ALAAYE LATI LE BA OBINRIN WON GBE
Lotito awon eda yi lobinrin won je elero meji, ki okunrin toba fe won, na se akiyesi iwa yi lara won
na. Awon obinrin abe irawo yi, ni eda kan to ni emi itara lori ibalopo, ahhh ibalopo ma ndabi ounje
lara won ni, ayafi eyi toba so abe re ati eyi ti awon obi re ko fun lati ma jade kaakiri.
Tori iwa ti nbe lara won yi lo ma fi n je isoro fun won lati fi oko won sile jade lo tabi lati rin irin ajo,
eyi ti koba so abe re ninu won ti oko re ba rin irin ajo olojo pipe hmmm osese ki iru obinrin be ma
yan ale, tori ara won ki n bale nipa ibalopo, nise lo ma n gbe won ni oungbe bi omi, gbogbo awon
oun tia ka sile yi lo ma nsele si won tori wipe won ko mo bi a se nfi iso so ife okan won.
Okunrin toba mo ogbon ete lo tabi bia se tan eniyan je nipa oro ife, hmmm yoo tete wole si ara awon
obinrin abe irawo yi tori okan won fele nibi ka gba oro ife wole si.
Bose wa ri yi, ti obinrin gemini bati ri okunrin tole ba se ere ife debi ti yoo te lorun, oun ti nse tan ni
yen koni wo ita mo beesini koni yan ale, amo laije be koni fi ojuire wo oko re oo.
Ibi to le de, ti obinrin gemini yi ati okunrin kan bati jo soro ife, ti won si jo je afe sona, ti afesona re
lokunrin ba je eni to ma nfi gbogbo igba bere ere ife lowo re tabi ti won bati jo nsere ife eyi to ma
nwaye ni akoko ti won ba rira won tabi to lo ki sile, hmmm fun rara obinrin nani yoo so fun afesona
re lokunrin wipe ki awon mu ojo igbayewo ni paapapa, tori ni fe ma ji obe je mo, yoo ti ni lokan lati
ma je toka-taya, ju ife oju ona ti won nse lo.
Eyi ni asiri iferan ti okunrin le sa si obinrin Gemini ti yoo si mu ni paapapa, asiri nani wipe: Obinrin
Gemini je omobinrin to ni opolo pipe tosi ni oye lori pelu, ti okunrin na ba fe ki ife oun tete gbinle
lokan re, yoo ni lati wadi awon oun kan ti obinrin yi koni imo nipa re rara tabi ko se akiyesi awon
oun ti obinrin yi ko mo, ki okunrin na wa gbinyanju lati ma ko ni eko na, wo iwo olukawe yi ma je ki
paro to okunrin na, gbogbo igba nani yoo ma wa lati ma gbo oro enu okunrin na latari eko tofe ko
lowo re, diedie ti eko na ba ti n wole si lara ummmm, ni oun tia n wa ba tewa lowo, yoo je tire ni
dandan ni. Tori omo eleko to fe ni imo ni awon omo yi je.

18
ITESIWAJU LORI ORO AWON OMO CANCER, IRAWO OMI
Alaaye adamo awon omo yi ni wipe: won je eda kan to ma nronu jinle, bee na sini won wa ninu
olotito eda, sugbon nipa kani igbonara awon na je okan lara awon toni igbonara, won laanu loju,
kosi eniti won kole se anu fun, amo opolopo igba loma njasi ibi fun won, niyi toun tunmo si wipe eni
ti won ba se ore fun osese ki iru eni be fi ibi san fun won pada. Tori anu towa ninu adamo won yi, ti
eda kan ba gbe oro de odo won, won ma mo bi won yoo se parowa fun ti won yoo si fi lokan bale,
won mo bia sele yanju oro larin eniyan ti kosi ni wahala.
Kowa si bi eda sema rin ti ori koni mi:
Aleebu awon omo yi nani wipe: igbamiran won ma daadi ti won koni dasi oro eni kankan lai si ki
nse wipe won nbinu. Ekun rere alaye oro yi nbe ninu iwe akoko tia mo si Taa Ni Mi????. Oun tofa ti
won fi nwu iru iwa yi gbogbo re lati salaye sinu iwe na. Awon omo yi na ma ni irewesi okan gege bi
ti iwa awon omo Gemini. Iwa adogbon mu nkan mora won nbe ninu iwa won.
Tia ba wa nsoro nipa aile dabobo tabi kama le toju asiri, awon omo cancer yi je okan lara won, enu
won ko bo rara nipa katoju nkan si eniyan lowo, kosi iru asiri ti won kole tu si eniyan lowo.
Tia ba wa nsoro nipa iferan, awon omo yi feran awon nkan wonyi: won feran ki won ma joko si eti
omi, ti won ba nri eni muwon losi eti omi, ife won yoo ma gbero si lokan won ni, eyi ribe tori ideda
won je Omi atiwipe inu omi ni alakan ma nsaaba gbe tori afihan irawo awon omo yi alakan ni (eni to
be fe iru awon omo yi, imoran mi sio nipe, gbinyanju lati ma mu lo si odo lati lo sere, to ba nse iru
eyi hmmmm wa ma ri iyato ninu aiye re niti dada).Won si tun feran lati ma se iranlowo fun eni ti
won ba feran julo, ibiti oro awon omo yi tun wa yani lenu si ni wipe, ti won ba njeun papo pelu awon
ore won tabi alabagbe won tabi katie ni wipe ni awujo, inu won yoo ma dun si ni.
Iwo toba ni iru awon omo yi ni iyawo tabi ore, gbinyanju lati sora fun awon nkan wonyi kio ma ba
ko sinu ibinu won, awon nkan wonyi ni won ko feran lati ma ri tori ti won ba nri inu won koni dun
beena sini okan won koni sure fun iru enibe, awon nkan tia nso niyi: won korira alejo ti won ko mori
rara, won si korira oro aburu ni siso nipa iya eni, eyi to buruju ni wipe, ti won ba fi oro si eniyan
lowo niyiti yoo fe ma dabi wipe won toju asiri si eniyan lowo, ti won ba wa gbo oro na nita tabi lenu
elomiran, inu ibanuje ni won ma nwa bee, ti won ko si ni ba iru enibe soro mon.
Tia ba nsoro nipa emi airi tabi kani asiri ikoko, wiwa agbara, awon omo yi je okan ninu won, emi
okunkun nbe lara opolopo won. Opolopo awon omo to jade labe irawo yi ni won ma nje omo omi ti
ibugbe won nbe ni isale omi, idi to fi ribe nipe inu omi ni irawo yi ma nsaaba gbe, gege bi moti si se
so ni isiwaju wipe alakan ni afihan irawo won, tia si mo wipe gbogbo isemi alakan inu omi lo ma
nposi si ju. Sugbon opolopo awon omo yi ni won ko kiyesi wipe omo omi ni awon, eyi toba tete
kiyesara yoo mo ti la awon ala ijaya kan, igbamiran won yoo sa dede la ala bi ki won bara won leti
odo nla, ki won ma sere leti omi, eyi to lagbara ju ninu ala won ni wipe, igbamiran won yoo la ala ti
won yoo si ma bara ni isale omi, aaahh iwo to ba se akiyesi iru ala bayi, ma mi kan rara ara won nie,
Agbara si nbe lowo re pelu iwo lowa kun si lowo bi wa se lo.
Ami ara a tun ma so awon miran latara ara won, tori ni opolopo igba ni won yoo lagun, ti omi yoo si
ma se lara won.
Hmmmmm, omo toferan omi ni awon omo yi.
Awon omo cancer yi, won kii ngbe nibi ti won ba bi won si fun ojo pipe tabi kani ilu ti won bi won
si, tori won je eda kan to ma ntete kuro ni agbegbe ti won bisi yaala lati ikoko tabi to ba dagba. Oro
enu awon omo yi ko dara to nigbamira, won ko mo oro kan lai nso, amo won ki nse alagabangebe
eda. Irinrin si won bi ti alakan ni, irin ese won ko ya rara.
Ikilo: gbogbo oun toba ti nise pelu apa osi ninu eya ara awon omo yi ki won sora fun, bi apa osi, eti

19
osi, ese osi, oju osi, ati beebelo, ki won sora gidigidi nibe, tori ibi ti won yoo ma fi sese ju ni apa osi
won (left sides).
Ki won si sora larin awon odun yi lati dawole nkan tori larin awon odun nkan ma nfe le koko die : 5,
25, 40, 48, 62
Iyipada rere nbe larin awon odun yi o si dara lati dawole nkan tori ere nbe larin odun yi: 4 , 16, 32,
36, 54

ALAAYE LORI BIA SELE BA AWON OMO CANCER LOBINRIN GBE


Ideda awon omo obinrin ti nbe labe irawo yi le fe nira die latara iba gbepo won, amo won je eniti
okan re ma nfa sile ti won si ma ronu nipa ile pelu, lotito nia so siwaju wipe awon omo yi je eda kan
ti ma ntete kuro ni ile tabi agbegbe ti won bi won si, toun tibe won ki ngbagbe ile. Ki awon obinrin
ti nbe labe irawo yi sora tori atako ti won yo ma ri, ki won si sora fun emi imo tara-eni. Awon obinrin
won, won ki ntete yoofe, amo ti okunrin bafile jere okan won, gbogbo aye won ni won yoo jule fun
won yoo si fe tokankan, koda ibiti ife awon obinrin yi lagbara de, ife ki tete kuro lokan won, ti won
ba fi okunrin kan sile wipe awon kofe fe fera won laije je wipe won ni ija kan titele, hmmm ti won ba
tun pada rira won, ife won yoo tun pada (E lo ka ekunrere oro yi ninu iwe Taa ni mi ???? ni abala tia
ti soro ife ati ifarakanra won). Okunrin toba fe awon omo yi ko gbinyaju lati koko ko enu ife si, tori
ki won bale tete mo wipe enina nife won.
Gege bia tise so wipe,won ki ntete yoofe to, ara won ma nse girigiri nipa ibalopo ni, atiwipe won ki
nfi gbogbo enu soro, opolopo igba ni awon omo yi ma fi ero won han ni ilana ibalopo, ti won ba ri
okunrin to rewa dada, hmm ara won ki nbale rara, papa julo awon okunrin ti ewa won nbe ninu
eyinju won. Hmmm, ti okunrin bafile raye jere ife okan awon omo yi, mo ki ku orire. "Awon omo yi,
ki nse obinrin to ma nsere (Ibalopo) ekan pere ti yoo si so wipe otito, rara koribe, won kole pe lodo
okunrin ti nba se iru eyi".
Okunrin toba fe jeki obinrin cancer pe ni ode re, yoo ni lati je olotito eda ati oniteriba.
Okunrin toba daa (betray) awon omo yi, laye won koni gbagbe re lailai.
ALAAYE LORI BIA SELE BA OKUNRIN WON GBE
Ohun akoko tia koko lo mo ni wipe, eni toba fe ba awon omo yi se, oun ni yoo koko ko enu si. Awon
okunrin ti nbe labe irawo yi ma nberu lati gbo esi idakeji oro dipo esi ti won ba nreti. Opolopo ninu
awon omo okunrin yi je onikanra, won si je eni to ma ntiju pelu, bee sini won mo bi won se kora won
nijanu.
Tia ba nsoro nipa adufe, awon okunrin ti nbe labe irawo yi je okan lara won, hmmm, opolopo
obinrin lo ma denu ife ko awon okunrin abe irawo yi, agaga eyi toba je alawo pupa ninu won, won
koni ko enu si obinrin ti obinrin yoo fi ko enu ife si won, amo bose je wipe obinrin ma nfe denu Ife
ko won nigba gbogbo, obinrin toba ma sebi iya fun won ni won ma nwa lati fe gege bi iyawo, niyi ti
o la fa ki won je eni ti yoo ni afesona to po latari wipe won fe wo eyi ti yoo je obinrin rere ninu won,
ati eyi tole se bi iya fun won.
Ao ma ri awon aleebu yi lara awon omo wonyi:
Irewesi tabi ki won ma sebi eniti inu re kodun, eyi lo ma nfa ni opolopo igba ti won ki fi ki (Greet)
arale won, won ko momo ma wu iru iwa yi, amo adamo won lo so won da be.
Ero buruku ma nsaba wasi okan awon, ti won ba nreti nkan, idakeji re ni won ma ro lokan won, won
si tun je enikan ti ara won yo mo eda.
Obinrin toba fe jeki ife gbinle lokan awon omo yi, obinrin yoo ni lati woye si gbogbo oun ti okunrin
yi ba nse nise,iwa re, ati oro enu re, latari nkan meta tia kaale yi, nigbakugba ti won ba jofe soro, ko

20
mu okan ninu awon akole meta tia ko soke yi kofi ba won jiroro, eyi ni yoo mu ki okunrin abe irawo
yi woye si oro omobinrin na wipe "Iya eyan nikan ni yoo ma bani da iru amoran bayi".

ITESIWAJU LORI IRAWO AWON OMO LEO (IRAWO INA).


Alaaye adamo awon omo yi ni wipe: Won je eda kan toni ogbon atinuda lara, ti won ba ri nkan won
yoo ma wa ona ti awon le gba lati le fi tun nkan da si omiran. Won ni emi itara na lara, won nbe ninu
awon oninure eda, ero rere ni ma saaba wasi okan won, oloyaya ni won, won a si ma je aderinposonu
tia mo si alawada omo.
Amo aleebu awon omo yi kun die kaato, eyi si ma sele lopolopo igba ti won ba wa ni ipo ibinu ti
okan won ba fun ibanuje, lara awon nkan ti yoo ma sele ni yi: iwa agidi okan, agidi okan won le dibe
pe won ni fe gba oro elomiran mo ti won, sugbon toba ba omo gemini pade oun lo ma le kapa re,
onigberaga, afemi-afemi, ole (lazy).
Awon nkan wonyi je oun ti won feran julo: ile-ere-oritage ti awon oloyibo npe ni theater, won si tun
feran lati ma wa lai sise kankan ti won yoo ko ma je igbadun. Ti awon omo yi ba soro kekere kan
tabi won wa ni awujo kan, idunu ma nbawa latari wipe ki awon eyan to wa ni agbagbe na ma fi ife
han siwon, eyi lo fa lofi je pe opolopo igba tiwon ba wa ni awujo eniyan won yoo wa oro kan lati so
lati file pe akiyesi awon eniyan ti nbe ni agbegbe won. Eyi ti Olohun ba bukun ninu won, awon nkan
to gbowo lori lo ma nife si lati ra, ati awon nkan to ma ntan yoroyoro.
Awon wonyi losi je awon oun ti won korira tabi ti won ko nifesi lati ma ri, gege bi iwa awon eniyan:
Won korira ki eniya ma foju pawon re. Idamu nla loma nje fun won nigbati won ba koju isoro kekere
kan, okan won ma nbaje gidi ni ti won bati wa ni ipo yi.
Eyi to wa gaju ninu re ni wipe, bi oba/olori (queen) ni won ma nfe ki awon eniyan se ma ke won,
won korira lati ma ma se itoju won bi oba tabi Olori, idi tofi ribe ni wipe planet toun dari irawo yi je
orun, niyi ti orun si nse afihan oba ninu eya re.
Awon omo yi ma nsaba ga, igbaya won si ma fe. Bee sini egungun ara won ma nsaba le, tori planet
ti ndari irawo won je planet ti nse ipase egungun lara eda. Eyinju won ma rewa beesini imu won ma
nsaba tobi.
Ise bi ise Ologun lo ma wu won se, bi awon agbofinro tabi ki won ma du ipo olori.
Ere die lo ma nte won lowo lori ise ti won ba se, amo won ki ri ijakule ninu re.
Won feran irin-ajo. Ti awon omo yi ba nwa oko, ere won ma jupo ni popo.
Igbega ma npe ko to ba awon omo yi, iyipada rere ma saba ba awon omo yi ni igba ti won ba wo
omo ogbon odun (30 years) lo si oke. Won ki ni molebi pupo.
Ki won sora fun iwa inu bibi ati ojowu, ki won si sora lati ma wu iwa buburu si awon alabagbe won.
Larin awon odun yi, ki won sora lati dawo le nkan tabi lati rin irin ajo, tabi lati kowo le ise kan, tori
larin awon odun yi, esi rere ki nsaaba waye nibe fun won: 5, 13, 28, 36, 48
Awon odun yi lo dara fun won lati gbero rere, irin-ajo, ise ati bebe lo: 10, 15, 25, 39, 53, 66.

ALAYE LORI BIA SE LE BA OKUNRIN LEO GBE


Awon okunrin ti nbe labe irawo yi feran lati ma jeki eniyan se itoju won gege bi oba.
Ni won igba ti obinrin (iyawo) bati se akiyesi, ija koni ma waye larin oun ati okunrin ti lo irawo yi.
Gbogbo ero (plan) obinrin to ba wa lodo awon okunrin yi, gbodo je ero nla pelu igbese to yege.
Obinrin na si gbodo ma fi ife han si, ifokan tan, ati iteriba fun won, tori awon okunrin won le pupo,
ti obinrin na ba nse iru nkan yi fun koni si iyonu ninu ife won.
Awon okunrin won ma nje oninurere won ma fi ife han si awon iyawo won latari ebun rira fun. Bo

21
ba se wa nse eyi fun obinrin, obinrin na si gbodo fi han wipe oun yoo ma toju re gege bi oba. Awon
okunrin abe irawo yi feran ki won ma yin won ni igbakugba ti won ba farahan si eniyan tabi ti won
ba se nkan. Botilejepe won ma farahan pelu igboya, sibe won tun ma reti ki eniyan gbe oriyin fun
won.
Lara won ebun toda to wa lara awon omo yi re: won lotito won si ki jarafa nigbi ka fi ife han tabi
ifarakora (they are romantic), ti won ba ni iyawo meji, eyi ti o ba nse itoju re koto jade, nipa koma
wo aso ti okunrin na yoo wo jade tabi koma se akiyesi si imura re, iru obinrin be ni okan re yoo ma
faasi ju.
Awon okunrin yi ma saaba je apon (bachelor), amo apon ti won ki se eyi ti ko ni fe iyawo s'ile oo,
apon ka ma woye si obinrin tia fe fe ni won je.
Igbese aiye won kun fun ajoyo ati ayeye, won ni anfani lati pe akiyesi awon eniyan si odo won, niyi
ti yoo ma mu awon eniyan feran won, eyi losi fa tofi je wipe opolopo obinrin lo ma nfe fe awon
okunrin yi, koda ti iyawo won ba woye dada yoo ri wipe oun nikan ko ni oun fe okunrin na tori
obinrin ma npo fun won gan. Idiniyen ti won fi je (Adufe).
Lati le bori re, ki obinrin na ka oro nipa okunrin yi kosi woye si ise si, latara isesi yi ni yoo ti mo oun
to nfe. Se itoju re bi oba, kosi je tire titi lailai. Tori oba ni planet ti ndari irawo yi.

BIA SELE BA OBINRIN LEO GBE.


Igbesi aiye obinrin leo kun fun awon nkan to dara bee sini won ni idakeji na lara.
Awon obinrin abe irawo yi na je obinrin ti ma nwuyan lati fe, ewa ara won ma dani lorun gege be
nani okunrin won se ri, kosi oju toba ri won ti koni nife won, ayafi eyi ti won ba fi ikorira si ara re
nikan lokun.
Awon omo yi feran lati je eni ti araye yoo ma teju mo, oun lo ma nfa ti won ba fe jade, ni won se ma
mura debi wipe kosi odo eni ti won ma gba koja ti won koni wo won tori ewa ara won nkan ni.
Tia ba ri okunrin tofe ma sebi oko fun obinrin yi, yoo ni lati ma ba soro lorekore yoo si gbodo ma ra
nkan meremere ti njoni loju, tori awon nkan wonyi ni yoo ma fi ro wipe okunrin na mu owun gege bi
Olori (Queen).
Obinrin won ma nferan okunrin to mo ere se dada, won si ma nfe koje wipe awon ni yoo ma wa ni
ookan aya ololufe won.
Biba awon obinrin yi rin irin-ajo ife, eyan ni lati gbodo sora nibi toba kusi, ati gbogbo asise re, won
ko kin nifesi okunrin toba nfi gbogbo igba so abawon ara won tabi ibi ti won ku si. Won si feran ki
won ma gbori yin fun won gege bi awon okunrin won na se nife si iru nkan be.
Won korira lati ma ba okunrin du oko tabi ki oko won ma yan ale, dipo re ki won ma ke won bi Olori
(Queen) ni won nife si ju.
Lati mu ife won gbinle dada si:
Gege bia tise so si oke, awon obinrin yi feran oun to rewa ti si njoni loju, paapa julo, ibi ti won ma
nko awon nkan bi ere ati awon nkan aiye atijo si tia mo si (Museum) tabi ile ounje to gbajumo dada.
Eyi taba raye fun ninu won, kia ra ododo (flower) wale fun tabi ounkoun tia mo wipe o ma mu inu re
dun.
Amo oo ti obinrin na ba se akiyesi wipe okunrin na kofe na owo fun owun eyi lemu ki o ko oko na
sile.
Awon obinrin yi le fe ya onijogbon die tabi kofe je apase lori oko re, okunrin na yoo ni lati da bi
ogbon bie ni nfun laye lati ma pa awon ase diedie, tabi ko file ko ma dari nkan, papa julo ki oko re
ma gbinyanju lati bere ibere lowo re. Ti okunrin na bale ma se iru awon nkan wonyi, to si toju re

22
gege bi olori (queen) ife to jinu yoo ma be ni arin awon mejeji.

ITESIWAJU LORI LORI ORO AWON OMO VIRGO


Awon omo yi na je olotito eda, alawofin, won a ma woye nkan dada ki won to fi esi si, iwa daradara
ni nbe ninu iwa won, won ki nfi ise sere rara, won ma sise takuntakun.
Aleebu die towa lara won nani: won je olojuti eda, won si ma dara won lamu lori oro won ati oro
elomiran nipa wiwa ona abayo tabi aseyori si oro na, ki won sora ni arin yi. Ti won ba nsise lowo
won ki nfe simi rara ayafi eyi ti koba wun won se nikan lokun, awon ni Oloyinbo npe ni (All work
no play).
Lori kie feran nkan: awon omo yi feran nkan isin ati awon eranko, ati ounje to lalaafia, won ki nfi
inu won sere rara nipa ounje, eyi toba kawe ninu won, yoo feran iwe kika, won si tun ma ni igbagbo
lori awon oun ti Olohun seda ti ki nse atowoda, ninu ka feran imototo awon omo yi na jekan nibe.
Lara awon oun ti won korira ni awon nkan wonyi:
Won konife si awon oniwa buburu tabi awon ti won ba ntapa si ofin, hmm opolopo ninu awon omo
yi ni ko feran ki won ma wa iranlowo losi odo elegbe won, ti nkan ba ndun won lokan tabi ki won
nilo iranlowo kan won ki nlo ba enikeni, ayafi eni ti won ba nifesi tia le pe ni ololufe won.
Awon omo yi ma saba tete pe akiyesi ara won sibi nkan tabi kani eko kan, atiwipe ogbon ijinle ti nbe
lara won lo mu won je irawo to ni ifura ju ninu gbogbo irawo to wa. Won ni ogbon ati oye bia se le
ko opo eniyan jo. Niwoba igba to je pe Mercury ni planet ti ndari irawo yi, idire re ti awon omo tia bi
ni abe irawo yi yoo fi ni Agbara lati le soro dada ati lati la ko iwe.
Ti awon omo yi ba nri, won ma saba te orun won ba, tabi kani won ma teriba nigbati won ba nrin.
Awon omoyi kundun erin pupo, ti eniyan ba won oju won, erin ni eniyan yoo ma ri ni oju won. Oro
enu won si daa saka. Igbamiran awo ara won ki nsaaba dan, niyi to jasi pe bi kokoro ma n fe sewon
ni ara (Eyi ribe tori planet to ndari irawo yi "Mercury" ni, oun si je planet toun se ipase awo ara eda
(skin), ti planet na ko ba wa bose ye kowa, o le fa kokoro ara si won lara ti awo (skin) ara won kosi
ni dan.
Awon omo na ni suru doju amin amo ti inu won bati ru lekana bayi, ibinu won soro lati da pada. Won
ki tu asiri won fun eniyan.
Hmmmm, igbeyin awon omo yi lodara ju.
Larin awo odun yi ki won sora lati dawole nkan tabi lati rin irin ajo, tori olewu pipo: 4,16,23,36,55.
Larin awon odun yi nkan dada yoo ma sele won ti won basi dawo le nkan ere nbe nibe fun:
10,15,25,39,53,66.
BIA SELE BA AWON OKUNRIN WON GBE
Tia ba ri eni to ni wipe oun fe ba okunrin yi gbe, yoo ni lati je eni toni imototo.
Lotito awon omo yi ki ntete yoofe be sini won ni ifura. Idi ti won ki nfi tete yoofe ni wipe, won ma
deeju sile dada ki won to ni wipe awon yoofe lagbaja tabi okan lagbaja nfa siwon, won yoo wo
finfini ki won to wo inu ibudo ife lo.
Lara awon nkan to dara ninu iwa awon omo yi re: won je okunrin tose gbe ara le, won ni ogbon ijinle,
won si ni oye lori, iwa omoluabi nbe nini iwa won.
Eyi si je idakeji iwa tao ma ba pade lodo won: won ma nberu,won ma saaba gba oro sodi.
Awon obinrin toba fe bawon gbe yoo ni lati ni opolopo suru nigbati okunrin abe yi ba nbinu lowo,
too ba ni suru fun ara re yoo pada wale.
Ti obinrin ba je, olotito, onisuru, ati eni tole ko opo eniyan jo, tosi mo itoju ile se dada nipa ima se
inu ile ni imototo. Ti Okunrin abe irawo yi bafile yoofe obinrin na hmmm, loba pari, tori ife olojo

23
pipe ni okunrin na yoo ba lo.

BIA SELE BA OBINRIN WON GBE


Ideda awon omo yi na se gbarale. Ni igba akoko tia eniyan ba fe ma ba awon omo yi gbe tabi fe denu
ife ko won, yoo koko mu bi iberu dani tabi ijaya, tori koni fe koko fe gba iru aba na wole. Eyi sile ko
irewesi okan ba okunrin tofe denu ife ko.
Fun idi eyi, okunrin toba fe fe won, kogbodo gbe si okan wipe yoo tete gbo toun rara, won le die
nipa oro ife. Okunrin na yoo ni opolopo suru ti yoo fi gbo tire, amo ti obinrin na bati ri wipe okunrin
na ntele oun ju, yoo pada tun ero ara re pa, ti yoo si gbo ti okunrin na.Toba tiwa gba tan, yoo se ike
oko pipo yoo si ba lo pelu ife otito.
Ibiti asiri won pamo si ni wipe, won ma nife si okunrin olopolo pipe tosi ni imo ijinle tabi imo koko,
tori oun na yoo ma ni lokan lati ko eko kan si meji lara okunrin na, ti won ba ba iru okunrin bayi
pade, won maa tete yoofe re.

ITESIWAJU LORI ORO AWON OMO LIBRA


Iseda awon omo yi ni pe, won je enikan toferan ifowosopo pelu elomiran, won si tun feran oro oselu,
won ni aanu omolakeji loju, won si tun feran oun aiye tabi kani afe aye.
Aleebu won ni pe: won ki nfe dase pa lowo ara won, won ki nfetele ero okan won, won ki fe koju
awon eniyan nigbamiran, won ki ni itelorun. Ibanuje ma gbokan won so nigbati won ba wa ni inu
isoro kan.
Eyi nbe lara nkan ti won feran: ifowosowopo, oniwapele, won si feran ki won ma jiroro larin
eniyan nkan ti won ko ba mo, won yoo lo woye si eni to mo lati gbe oro na ye wo, opolopo ninu
awon omo yi ni ko feran komo joko sile, bi ita bi ita lo ma nse won.
Won korira awon oun tafe so yi: won korira iwa ipanle, bee sini won korira aosotito, bi ifihan irawo
won se je osuwon idajo, idi re re, ti won fi korira iru awon alaisotito eda, won tun korira eda ti ma n
pariwo, tosi jewipe ariwo toun pa taba wo lo wo bo, iro ni ao ba nibe. Awon omo yi je oniwapele,
itosona si ma wa nba awon omo yi latari ima ka iwe, bi iwe asiri tabi iwe to nise pelu igbesi aiye.
Awon omo yi ki saaba sanra won si ma nga.
Olotito ni awon omo. Won ni ebun nipa kama fi emi dari nkan.
Won ni ogbon ironu pelu isedede larin gbogbo oun ti won ba nse. Won ki soro pupo amo won ni
igbagbo ninu nkan ti won ba fi oju ri ju oun ti eniyan nso loro lo. Eni ti won ko tosi gbo eko ye ni
awon omo yi, won ma se iranlowo fun eni ti olohun bani ki won ri iranlowo se fun paapa julo awon
eniti won ko ri owo mulo senu, ati awon arugbo ti ojo ti lo lori won. Awon omo yi ni igbagbo ninu
esin dada.
Nigbati awon omo yi ba bere sini dagba nkan ma nsaba le die fun won, amo iranlowo ma ba won
niwonba igbati won ba ti n wo omo odun 32 si 35 iyipada rere yoo ma tewon lowo. Awon eniyan ti
nbe ni ipo nlala lo ma sanu fu awon omo yi, bi ki won ma ri anu gba lati odo ijoba, oba ilu, bale, ati
beebelo.
Olohun saba ma ngbe won pade olulofe to lowo.

ALAYE LATI LE BA OKUNRIN WON GBE


Oun to je adamo won ni wipe, won je eda to ma wa aseyori si oro eyan. Akoko ninu oun ti obinrin
toba fe ba awon omo yi gbe ni wipe, obinrin na gbodo je eni too dun wo loju tosi rewa papajulo
obinrin to mo ara mu.

24
Gbogbo oun toba jomo nkan to rewa loma wu awon okunrin yi. Obinrin ti koba mo ara mu nipa ka
se oge ora, obinrin na kole pe lodo awon omo yi, koda koni wu won rara.
Aleebu nla ara won ni wipe, won ki nle pinu lati se nkan, idi re fun obinrin toba fe fe won gbodo ma
gbaruku ti won ni gbogbo igba ti won ba nfi ero okan won han.
Awon okunrin abe irawo yi, ma n fe jiroro pelu ololufe won, amo ti oro na bi ti jinle to je oro asiri,
esekese ni eru yoo ma ba won.
Awon okunrin yi oro siso koki nse isoro fun awon omo yi rara, amo abo oro lo to fun omoluabi won.
Obinrin toba nife won ko sun mo won kosi so ero okan re fun won.
Oun kan ti obinrin le fi je tire lailai oun ni wipe yoo ni lati lo mo ara mu dada, ko mo ara se loge
daadaa kosi ni igboya.
Ni igbakugba ti okunrin yi ba (obinrin/iyawo) re lebi oro kan, tete gbo si lenu, ko si gba wipe lotito
o jebi oro na.

BIA SELE BA AWON OBINRIN WON GBE


Awon omo yi feran lati ma je wipe awon ni yoo ma je oun akoko ti oko won yoo ma ro. Awon na si
nifesi lati ma se itoju won gege bi Olori (Queen) bi ti awon omo leo, idi to fi waye be ni wipe, planet
venus ti ndari irawo yi je omo oba (Princess) ninu afin planet amo omo oba ni planet yi ki nse aya
oba.
Okunrin na si gbodo je sorosoro ni yi ti yoo ma so oro nipa obinrin na.
Awon omobinrin yi kundun lati ma ko eko ti won ko mo tele gege bi awon obinrin virgo.
Awon omo yi ma nwu yan pupo, won loye won si je eni to ma nwa aseyori si oro eda gege bi okunrin
won se ma nse.
Nigbati oro ife bati wo larin obinrin yi ati okunrin, oun to tele ni ibalopo, tori toba ti ni beeni,
ibalopo ni yoo ma wasi okan re.
Lara awon nkan to ma ti ma wu awon obinrin yi lori owun ni wipe, ki oko won ma yin won pelu ewa
era won.
Gbogbo nkan ti arabinrin yi ba fun oko re gege bi imoran ni okunrin na ma gba, tori obinrin abe
irawo yi ni yoo ma je itana ogo fun oko re.
Iyen toba fe okunrin onirawo ina loko.

ITESIWAJU LORI IRAWO AWON OMO SCORPIO.


Awon omo to wa labe irawo yi na je eda kan to se gbokanle won ki saaba da eiyan. Won si ni igboya
gege bi awon omo Aries, nkan ki bawon leru, won ni itara nkan lara, awon na si ni agidi pupo, ibinu
won ko yato si ti awon omo aires amo ti won tun wa peleke ju ti awon omo aires lo, tori ifihan akeke
ni aworan ti irawo won gbe wa, inu bibi won si dabi ti akeke ni. Nipa ka je olotito ore (friend) won je
okan lara awon olotito.
Aleebu ti wa nbe lara awon omo na ni wipe: won je eda kan ti ki ntete gba elomiran gbo, won si je
eda ti ma njowu, okunrin won yoo jowu lori aya re be sini, obinrin won yoo jowu lori oko re tabi lori
nkan ti won koba ni, awon omo yi mo bi won se ntoju asiri sowo, ti asiri ba wa ni owo won, o soro
lati mo tabi lati ko lodo won. Eyi ti koba kora re nija nu, iwa ipanle ni yoo ma wu, yoo si feran ko da
nkan ru, aleyeyi nbe ni oro lori planet iyen ti mars, tori mars lo je Oludari irawo yi gege bi planet re.
Wonyi ni awon nkan ti awon omo yi feran lati ma ri lara eniyan tabi lati ma ba pade nibi ti won ba wa:
Won feran lati ma gbo ookodoro oro lenu awon eniyan, won si ma nferan awon ore won ti won tijo
wa tipe ju awon ore ti won ba sese ni lo, won feran ki won ma tan eniyan tabi ki won ma ga yan.

25
Wonyi si ni awon oun ti won korira lati ri tabi lati ba lara awon eniyan: won korira eda ti ko ba ni
ododo, ati awon eda eniyan ti won ko mo bi won se ntoju asiri, paapajulo enitoba ma ntu asiri, won
ki nfe je ore (friend) fun iru awon eniyan bayi, bee nani won kole ba eniyan ti koba ni emi itara lara
gbe po.
Awon omo yi na je enikan ti ma nfimu finle lori nkan ti koba ye won tititi won yoo fi ri okodoro oro
na.
Tie ba ri awon omo yi, awon ni eyi won ma nsaba tobi dada, ti won si ma ni agbon (jaw) to tobi, won
ki dudu ju, pupa won ferefe ni, won ki nga ju, giga niwonba ni, won si je eda to ma ni ora lara dada,
idi ni yen to fi jepe osese ki opolopo won tobi.
Awon omo yi ma saaba wa ise ti won lo chemical fun gege bi awon omo onimo ijinle tia mo si
scientist, won tun ma nife si ise ologun, orire nbe fun won ninu owo sise.
Nigbati awon omo yi ba nfa wahala lowo, won ki nko nkan ti yoo ti eyin re yo. Ki won sora fun
ifekufe nkan ni jije, tori ilera ara won. Nigba miran ti won ba nsoro, oro enu won ma nfe dabi pe oro
radarada tabi oro ebu, ki nse wipe won momo so iru oro yi, bi ideda won seri ni yen. Ti won ba nsise,
won ma ntete pari ise won, amo ona ti won ma ngba sise won ki n te awon elomiran lorun.
Opolo awon omo yi ma nji pepe nigbati won ba nko eko, eko si ma ntete ye won. Opo ninu awon
omo yi ni won ki ni iba gbepo to dan moran lari won ati molebi won lokunrin tabi lobinrin paapa
julo awon toba je aburo tabi egbon fun.
Ki won sora tori won le ni apa ni apa ati ni ese. Won feran nkan bi aajo tabi oun toba ti jomo ogun ni
sise.
Ki awon omo yi sora larin awon odun yi lati dawo le nkan tabi lati rin irin ajo :
11, 28, 38, 52, 62.
Awon odun yi dara pupo fun ti nkan rere yoo si ma te won lowo : 8, 23, 32, 44, 64

BIA SELE BA AWON OMO SCORPIO GBE PO


Enikeni to ba nwa lati le jeki awon okunrin abe irawo wun won tabi ko ni fe won, ki nse oun to rorun
rara.
Awon Okunrin Scorpio yi, ibagbepo won ki nse eyi to ma mu efe dani, igboya nbe lara won,
alagbara ni won, won nife ibalopo, won si tun wa je eda kan to feran ifigagbaga.
Eyi to je alebu won ni wipe: won ko ni ikapa emi won nigbati won ba nbinu lowo.
Fun idi eyi, obinrin toba fe bawon gbe yoo ni lati, se oun aramanda nigba gbogbo niyi ti yoo ma mu
ori omo okunrin na wu.
Ipenija je lara awon nkan ti obinrin yoo ma ba pade lodo awon omo yi, idi ni yen ti obinrin toba wa
pelu won gbodo ma reti wipe igbakugba ni oun le ri ipenija lati odo awon omo yi.
Amo, bia se wa so gbogbo awon nkan won yi, obinrin na ni lati fi iwa otito, isemi ododo, ife
afokantan ba awon omo yi lo.
Awon okunrin abe irawo yi ma nsaba wun awon obinrin toba ni igboya ati awon eni ti won nife si
kama fera eni soju ona bi ale yiyan.
Taba ni ka soro nipa ibalopo, awon omo yi je okan ninu awon to gba ipo kini. Ati wipe abe (Nkan
omo okunrin ati nkan omobirin) lo ndari irawo yi, tori na ki won sora nibe.
Ikilo: Obinrin toba fe ba won gbe pe titi, eewo ni lati ma pase fun awon okunrin yi, obinrin to ba nse
iru eyi o fe fi owo arare fa ijogbon ni yen oo.

26
BIA SELE BA AWON OMO OBINRIN ABE IRAWO YI GBE
Gege bia tise so lati oke wa, awon omo yi je alasiri omo, won ma wun eyan, opo eniyan losi ma nfe
lati fi won se aya.
Won je alaanu won a sima pinu lati ma se rere ni aye ti won ba bara won lorilede aiye.
Tia ba ri okunrin to fe bawo gbe, yoo koko ni opolopo suru, okunrin na yoo si gbodo fun obinrin na
laye lati se ise topo ninu irin ajo ife na.
Gbogbo oro ti awon omo obinrin yi ba nso ni oko won gbodo feti si.
Lotito awon obinrin je enikan to nife si ife pipo amo, won koni tete gba, tia ba ti ba oro ife bo pelu
awon omo yi, e ko gbodo tete bere fun ibalopo oo, ki won ma ba fi igi gun ife na.
Ti awon omo yi bafi le gba fun okunrin tan, gbogbo oun ti won ba ni ni won yoo fi ba enina lo titi
kan oun ini won.
Okunrin gbodo lo otito pelu awon omo yi, okunrin na si gbodo kora re ni ijanu nibi kia ma se
ariyanjiyan, tori ti ariyanjiyan yen bati poju, yoo so di ibinu ni, bee sini won je eda kan ti ntete
gbagbe oro, beesini won ki ntete dari jin eniyan.
Won ko ni itelorun to dada, won ma nfe firan si ipo giga ni, larin yi oko won gbodo dabi ogbon lati fi
won sile pelu iwa igbaraga die tofe wa lara won. Ti oko won bati se akiyesi yi, obinrin na yoo fun
won ni owo (respect) won, yoo si ba kale.

ITESIWAJU LORI IRAWO AWON OMO SAGITTARIUS.


Awon omo yi je oninure eda ti ma fe ore fun awon eniyan, oye nbe lori awon omo yi, won si ni opolo
bia tise ndunu ninu, ati bia ti se ngba ni niyanju lori ero kan si omiran.
Aleebu awon omo yi wa ni pe: Opolopo igba ni won ma nse ileri fun awon eniyan wipe awon yoo se
nkan bayi fun won, tosi je wipe won ko ni pada ni emi tabi agbara lati mu adehun won se, idi re ti
opo ninu won ki saaba fe mu ileri won se tabi ki won ma so ju oun ti won ba le se lo.(Larin yi awon
omo yi gbodo ma kiyesi ara won nigbati won ba n gbe adehun pelu eniyan ki won ma ba di opuro
niwaju awon eniyan). Ki won si rora ma binu tori ibinu won kodara to, kosi oro ti awon omo yi kole
so si eniyan koda ti oro na koba ba lakaye mu won yoo sa ri wipe awon so nani.
Ninu awon oun ti won feran lati ma ri tabi lati ma ba pade lodo awon eniyan re: won feran ki won wa
ni ominira ti koni je wipe awon eniyan ni yoo ma pase fun won, won si tun je eda kan to nife si irin
ajo pupo, amo irin-ajo won ma nsaaba je eyi ti ki se olojo pipe ati wipe irin-ajo won ma saaba da lori
oro esin tabi iwe, latari lilo ile mimo fun ise esin ati lilo ilu okere fun iwe kika.
Won feran gbogbo eko to ba ti ma mu ogbon wa fun won, idire re ti awon miran ninu awon omo yi
ma fi wa imo kiri. Opolopo igba sini awon omo yi ma fe wa ni ori orin tabi ijade, won ki nfe duro
sile.
Wonyi si ni awon nkan ti omo yi korira ti won ki si fe ri: won korira awon eniyan ti ma nfe sumo
won ju, won ma saba yera fun iru awon eniyan bayi tori won yoo ro wipe jamba ni won fe se fun
awon. Awon omo yi ki nfe ki eniyan ma tepele nkan mo won ju tabi ki won ma je won nipa lati se
nkan.
Awon omo yi ma ni ifiyesi, idunu ati orire ninu irin-ajo aiye won. Won si je onigboya, ologbon
ironu jinle, won si ma saba je olori ni aiye ti won ba wa, aisan ko ki nse ore ara won rara, idi re re ti
won ki nfi saaba se aisan ninu irin ajo aiye won.
Awon omo yi ma ngbajumo gidi laye okiki won si ma nkan daradara latari ise owo won ati imo ijinle
ti nbe lara won. Olotito ni won, won si se gbarale. Opolopo irori won ni ma saba wasi imuse.
Won a ma bi pupo ninu awon omo yi si idile olowo, awon na si ma ya olowo, amo owo ti won ba ma

27
ni, ki nse ise owo won, bi ki won bun won ni ebun tabi ki won jogun re.
Irun ori awon omo yi ma ntete pa, won si ma sise lai reti ore lati owo enikan. Koda ti won ba je
olusowo, won se owo won pelu otito. Ire ma saba to won wa larin omo 22-23 years.
Ki won sora larin awon odun yi lati dawole nkan tabi lati rin irin ajo, tabi lati kowo le ise kan, tori ki
nsaba si aridaju wipe won yoo yorire sibi ire: 2, 10, 18, 31, 38, 42.
Nkan ire yoo ma sele larin awon odun yi, yoo si dara lati mu ninu odun yi lati se oun ti won ba fe se
tori ore yoo po nibe fun won: 9, 19, 22, 36, 45, 54.

ALAYE LORI BIA SE LE BA AWON OMO OKUNRIN SAGITTARIUS GBE


Awon okunrin abe irawo yi je okunrin kan to feran igbadun pupo, ti irin-ajo lilo si je oun kan to wa
lara won, oro esin si je oun ti feran pupo julo, yala esin abalaye, esin musulumi tabi esin kristieni,
won yoo koju mo ni, koda o soro lati yi okan awon omo yi pada kuro loju ona esin ti won ba wa.
Gbogbo ibi ti imo ba wa ni won yoo ma se ayanju ran re lo ko, tia ba wo inu iwe akoko tia ti soro
awon omo ojo ti won bi ni Thursday eo ri nibe na, eyi ribe tori planet Jupiter je planet kan to lagbara
nipa oro esin (Iyawo won na gbodo feran esin).
Gbogbo idawole won ni yoo ma yori si ire, ti won yoo si ma ba idunu pade ninu isemi aiye won.
Lara awon nkan tia ma ba pade lodo awon okunrin omo yi ni wipe: won ki ni ifaseyin rara ninu oro
won (ayafi eyi toba lowo ninu). Igboya nbe lara won. Ima kuro lati ibikan sibi kan, je oun to wa lara
won, idi won ki ngbe ibikan.
Obinrin toba fe gbe pe titi lodo awon omo yi, obinrin na gbodo se imoriya fun imo ijinle to wa lara
okunrin na (itumo: gbogbo imo toba ri lodo arakunrin yi, ko gbodo tabunkun re), obinrin na si gbodo
bowo (respect) fun ipinu awon okunrin abe irawo yi.
Eyi si je awon oun ti a tun ma ba pade lodo won gege bi idakeji won: won ki saaba bikita awon nkan
miran, ainisuru si nbe lara won, ibinu ojiji po fun won pelu, emi ni mo moju na kun iwa won
(over-confident).
Gege bia tise so tele wipe won feran ominira (freedom), eyi lofa tofi je wipe, won ko ki nife si
obinrin toba je ruth aboko ku, won ko nife si aroko ariyawo.
Gbogbo awon oro tia kale yi loye ki awon iyawo won se akiyesi si. Ti iyawo won ba si fe soro fun
won, ki won ro oro na dada ki won to so, tori sagittarius lokunrin je oloye lori pupo, to si mo bia se
nwo oye si oro.

ALAYE LORI ORO BIA SELE BA OBINRIN WON GBE.


Sagittarius lobinrin je awon obinrin kan ti awon na feran igbadun jije gege bi okunrin won, ara won
yo moyan dada, won si feran ode lilo tabi kani ijade. Opolopo won ma ni opolo, tabi se afihan ara
won lona toje wipe eiyan toba wa lodo won yoo ma si ma ro lokan re bia ni wipe won fi ife han si
won. Olohun koda awon omo yi da ironu rara, gbogbo ojo ile aiye won igbadun lo kun fun.
Awon omo yi na je olotito gege bi okurin won tise je olotito na, ti won ba si n soro jade lenu, oro ti
ndun won lokan ni won yoo ma so jade, won koni fi oro kan pamo rara.
Ikilo: Oko awon omo yi, ko gbodo de won mole rara tabi ko ha won ni eha, rara! e fi won sile ki won
ma jade, gbogbo igba si ni ki oko won ma gbe won jade lati lo je igbadun ara won.
Okunrin to ma nse imele tabi ti ko ja fafa kole fe awon obinrin yi, tori yoo ma su won ti won ba ko
wa lai ri oro so, eyi lo fi je wipe, awon okunrin Gemini lodara fun won julo lati fe, tori gbogbo oun
ti obinrin sagittarius wa, odo okunrin lowa lara awon okunrin Gemini.
Ti okunrin ba soro ife pelu awon obinrin yi, okunrin na kogbodo fun ni idi kan ti oun fi feran re oo,

28
tori obinrin na yoo ro wipe ti nkan tori lara oun ba shi lo, dajudaju yoo fi oun sile, fun idi eyi koni
gba fun okunrin na. Hmmm: awon omo yi won ki ni afesona kan lailai. Bi afesona meji si meta tabi
jubelo lo ma nwa lowo won. Kilo fa?
Idi re ni pe, won koni fe joko si odo okunrin ti ko ni mu inu won dun tabi ti koni fun won ni
omiranira, tabi ti yoo ma ha won mole.

ITESIWAJU LORI ORO AWON OMO CAPRICORN


Awon omo to wa labe irawo yi je eni to ni amoju to nkan, won si je omo to leko pupo, ti won si
gbeko, won mo bia se nse ikapa emi ara eni, kosi ipokipo ti won ba wa, won a ma kora won nijanu,
won tun je olusakoso rere, kosi ile-ise ti won ba dimu, ile-ise na kona daru tori won yoo dari ile ise
na pelu emi otito ati imo won.
Amo, ao ma ba awon nkan miran pade lara won gege bi aleebu won, mo mo tan (I too know), won
ma nse be eni wipe gbogbo nkan ni won mo tan (Know it all), ti eniyan ba se won hmmm, o ma npe
ki won to fori jin, koda eyi ti ese re ba buru ju, o sese ki won ko lati darajin enina. Awon na nbe ninu
awon eni ti won ma ro ero idakeji si oun ti won ba nreti.
Ninu ka feran nkan, molebi awon omo yi jewon logun gidi, won feran molebi won pipo. Won feran
nkan ibile (Tradition) gidi, gbogbo oun to ba jemo ibile ni ma wu awon omo yi julo. Orin gbigbo na
si je oun ti won nife si julo, ti inu won yoo si ma dun ni akoko ti won ba ngbo orin na. Won ko feran
lati ma se nkan tabi so nkan ti won ko ba mo.
Nipa ise owo sise ati ka nife si nkan ibile awon omo capricorn je asiwaju ninu re.
Awon omo ti nbe labe irawo yi, won ki saaba sanra, orun won ma ngun, eyin wewe ni nbe lenu won.
Egungun ara won omo yi ma gbo dada. Won ki n gbe ara won si ipo keke re. Won si je eda kan ti ki
nse segesege, oju won ma nduro sibi kan ni.
Awon amoye ati awon ariran ma saba jade lati abe irawo yi.
Won yoo ma koju aawo (rivalry) tabi ki won ma ri atako lodo awon eniyan ninu isemi aiye won.
Awon omo yi na yoo ma wun yan nigbati eiyan ba ri won.
Agbega yoo ma ba aye won lati 32-33 years.
Ti awon omo yi ba nsise won ki saaba tete pari re, sugbon ise ti won ba se, pelu igboya ni won yoo si
yori re si ire.
Awon agbajo onirawo fidi re mule wipe, won wa lara awon ti won ma ni molebi pipo.
Ki won sora larin awon odun yi lati dawole nkan tabi lati rin irin ajo, tabi lati kowo le ise kan, tori ki
nsaba si aridaju wipe won yoo yorire sibi ire:
5, 13, 27, 36, 57, 62, 67, 72
Nkan ire yoo ma sele larin awon odun yi, yoo si dara lati mu ninu odun yi lati se oun ti won ba fe se
tori ore yoo po nibe fun won:
10, 20, 34, 55, 65

ALAYE ORO LORI BIA SELE BA AWON OKUNRIN ABE IRAWO YI GBE
Awon okunrin won nbe ninu awon ti won ni ipinu lori irin ajo aiye won, won si je eda to lapon,
gbogbo ileri won ni lati de ipo giga laye, ati lati le jere gbogbo oun ti won ti se kale gege bi ise owo
won.
Awon okunrin abe irawo yi nife si nkan toje ododo ju iro buruku idi re lo. Eyi lo mu mi so fun
obinrin to fe ba okunrin abe irawo yi gbe wipe, yoo ni lati fun awon okunrin nani owo (respect) lori

29
bi won base ba won ti obinrin na yoo si tun re ara le lodo okunrin abe irawo yi.
Eyi je lara awon oun to dara tao ma ri lodo awon omo yi, oun nani iwa jeje, won a si tun ma se
akiyesi oro yekeyeke, latara akiyesi sise yi, ni ma nje ki won de ibi re ti won fe de.
Won ki teete fe kan lu agbami ife.
Ki obinrin toba fe gbe pe titi lodo awon omo yi fi aye gba won lati le je ki won fi ogbon ori won to
gbogbo eto aiye won, eyi si nbe ninu nkan ti ma n mu inu won dun ni opolopo igba.
Ki iyawo re mase gbagbe wipe a so wipe awon omo yi feran nkan ibile, fun idi eyi aya re gbodo je
eni ti yoo ba gbe pelu iwa re ni, kosi gbodo je aya ti yoo ma se iyemeji pelu re.
Nigba miran, won a ma fe lati ba eni ti won mo dada gbe papo ju ajoji lo, won si je eni to n iberu
idojuti larin awoju, tori na jeje won ni won ma nlo.
Lotito la ni wipe awon omo yi kii tete kanlu agbami ife, won a si ma wo oye si bi obinrin sele se
ikapa emi re si ni ona ibalopo, obinrin to ba je onisekuse won ko ki nfe iru won.
Okunrin won le je eni to tutu ati wipe ni akoko bere irin-ajo ife won, won le je eni ti yoo ma jina si
ololufe won, amo ni igbakugba ti okan won bati bale, gbogbo nkan won yi ni yoo yipada.
Won tun saaba ma nnife si eniti o ma ni ireti lori bi won se n se apero lati le de bi ti won fe de, ati lati
se alabakun fun lorin irin-ajo aiye won.
Ikilo: Sora fun akoko (Time) tori akoko lodo awon omo yi bi owo ni (Time is money).

BIA SELE BA AWON OMO OBINRIN WON GBE


Gege bi awon okunrin abe irawo yi se ri nibi ka kan lu agbami ife bee nani awon obinrin won ri, won
ki saaba tete wonu ife, enikeni to ba wa fe ki awon omo yi nife won, okunrin na yoo ni lati koko je
alawada okunrin to si mo bia ti nfi oro didun pani lerin, leyin eyi okunrin na yoo ni lati fi obinrin na
sile fun igba die lati yanda okan re fun, kosi gbodo kan-loju.
Ni akoko ti awon obinrin yi ba koko wa ninu irin-ajo ife yoo ma so emi ara re lati le ma bo si
owolowo ati wipe won ki fi akoko (time) won sofo lori eniti okan won ko ba bale le lori.
Si kiyesi iwo okunrin toba fe fe won, okunrin na yoo ni lati se iwuri fun latara ewa re ati oun
yoroyoro aiye.
Oun toje iyalenu nibi oro awon omo yi ni wipe, okunrin ti won ba kiyesi wipe o je eni to na owo
(spend money) bi eni to nka owo lori igi, iwa yi le fa ki awon obinrin abe irawo ko iru okunrin be
sile.
Oro elekeji ni wipe, okunrin toba nbere ibalopo ni akoko ti won ba dijo je afesona lowo, hmmm,
esekese ni yoo ti iru okunrin be kuro ninu aiye re.
Ara awon omo yi ma nbale lodo oko won, won ki kanju nipa ibalopo ooo, won je eda kan ti a gbodo
(you must) fun won laye lati yanda ara won fun wa ni igbati a ba fe bawon ni nkan po, (ibalopo
gbodo wa lati okan won).
Won feran okunrin oloye lori, eyi ni yoo wa mumi so fun oko won wipe ni agbakugba ti won wa
pelu awon obinrin abe irawo yi, o ti di dandan fun lati ma ba won jirojiro oro to mu ogbon dani to si
loye ninu pelu.
Bia tise so ni ibere oro wa wipe, won feran alawada okunrin, tori re lo wa fi je wipe oko won gbodo
je okunrin ti yoo ma pawon lerin. Iru okunrin toba le se oun tia wi yi fun awon omo yi , ku orire.

ITESUWAJU LORI AWON OMO ONIRAWO AQUARIUS


Awon omo ti nbe labe irawo yi je eni ti igbega ma saaba ba won, gbogbo nkan ti won ba nse tabi ti
won ba fe ra nkankan, iru nkan be yoo ma je ojulowo ise tabi ojulowo nkan, won ki nra panda oja.

30
Won tun je eda kan ti awon na ki ngbara le eiyan, won dangajia lodo ara won. Oro awon eniyan yoo
si ma je won logun popu.
Iwoba aleebu die ti nbe lara won nani, ibinu, ariyanjiyan. Die ninu won ki n loju anu.
Awon nkan wonyi ni awon omo yi feran lati ma se tabi lati ma ri: won feran ki won ma lo se faaji
tabi ki won jade lo je igbadun pelu awon ore won, die ninu won na yoo si feran lati ma ran omolakeji
lowo (oro yi nbe ninu iwe apakini). Gbogbo ayekaaye ti won ba ti ri awon ojogbon ti won nsoro, iru
aye be yoo ma wun won lati joko si bee sini won yo fera bale dada lati ma gbo oro enu won.
Awon nkan wonyi ni won korira lati ma ri tabi lati ba lodo awon eniyan: won korira eda ti nba ma
rora re pin wipe oun le se nkan bayi, koda awon gan fun rara won, won ki nrora won pin.
Ti won ba ba eniyan se adehun, won ki nfe ki enina da won, awon na si korira lati ma da wa lawon
nikan, gege bi ise awon omo Gemini. Eyi to gaju nibe ni wipe, ti won ba se akiyesi wipe eni ti awon
ma nba soro, ma nfi gbogbo igba se aigba (disagree) si oro won, iru eni be kole pe lodo won rara ti
won yoo fi jatuka.
Awon omo yi je eni to ma nronu dada, won a si ma pe akiyesi si oro ara won, won si nigbagbo gidi
nipa awon emi airi. Opolopo won ma gbe iwa won pamo. Awon ore ti won ma ni na ma saba je
awon eniyan to wa ni ipo nla.
Won ma wun aya/oko won lopolopo, o ma nse won bi ki won ma rira won ni gbogbo igba ni.
Imoran: Yoo dara ti awon omo won yi ba le ma se irin-ajo dada tori ori nbe nibe fun won dada,
opolopo ninu awon omo yi ma ni opolopo ona leti fi kowo jo, won ki nise kan lowo.
Ki won sora larin awon odun yi lati dawole nkan tabi lati rin irin ajo, tabi lati kowo le ise kan, tori ki
nsaba si aridaju wipe won yoo yorire sibi ire: 2, 28, 33, 48
Nkan ire yoo ma sele larin awon odun yi, yoo si dara lati mu ninu odun yi lati se oun ti won ba fe se
tori ore yoo po nibe fun won: 11, 25, 35, 46, 56

ALAYE NIPA AWON OKUNRIN ABE IRAWO YI


Lakoko eni to ba fe ba awon omo yi gbe, yoo ni lati koko mo iru iwa owo won, eyi toda ninu iwa
won ati eyi to kun die kato.
Awon iwayi nani: won feran oro siso, won si tun je eda kan ti eiyan le ku giri so wipe nkan bayi ni
yoo se.
Eyi towa je iwa buruku won ni: won kose gbarale, won si ni agidi okan, won buru, won si ki gba
imoran boro, lori oro won yen ni won ma nfe duro le.
Tia ba ri obinrin tofe ba won gbe fun ojo pipe, obinrin na yoo ni lati koko je eniti yoo woye si iwa
oko re ti yoo si ni suru fun gidi. Ti obinrin ba wa se aigbo si oro yi, okunrin na koni gbero lati fi ife
han si depodepo pe yoo ma mu wo yara re lati ba ni nkan po.
Gbogbo nkan ti awon omo yi ba fe se, okan (mind) won ni won ma saaba gbe si, won si wa nilo
olugbani-nimoran lati le fi agbega ba ero okan won.
Amo iru imoran ti obinrin na bafe gba okunrin yi, kogbodo je eyi ti yoo tako ero okan okunrin na.
Obinrin to ma npe lodo awon okunrin yi je, obinrin ti won ti mo fun ojo pipe, ti won si ti jo je ore
(friend) dada. Tori oro fife won ma saba bere lati odo eniti won dijo mora ri.

ALAYE LORI BIA SELE BA AWON OBINRIN ABE IRAWO YI GBE


Awon obinrin abe irawo je eda kan ti oun na je alawada omo, ti won si feran ki won ma yora (dress)
dada. Awon na won kose gbarale gege bi okunrin won.
Won je awon olubagbe laya gidi, awon na ki nse obinrin ti nse ekan ti yoo duro (nipa ibalopo), ti

31
won ba ri okunrin tole te won lorun dada nipa apa tibe, won yoo duro sinsin.
Awon obinrin abe irawo yi ma saaba wun okunrin pupo, fun idi eyi, oseese ki oko won ma ri idi won
kan si meji lati odo okunrin miran to mo awon obinrin yi ri, eyi si ma sele dada nigbati won ba jo wa
ni afesona, ti yoo fe dabi enipe won du obinrin na lati fe.
Imoran: ki oro yi ma wa ni okan oko won wipe, awon obinrin yi ma nfe ki won mu won gege bi
molebi ni, tabi bie nipe iya kan lo bi won. Lofi je wipe gbogbo won fe mo gbogbo ero okan oko won.
Asise nla ti okunrin la se ti yoo fi padanu ife awon omo yi nipe, ti oko ba je eni to ma saba bere nkan
ju nigba gbogbo lori nkan ki nkan, tabi ki oko re je eni to ma njora re loju gege bi awon Leo,
ibagbepo won yoo fe nira die.
Awon obinrin na ko feran lati ma ha won mole tabi dide mole, oko won gbodo fun won laye lati jade
lo ibi to ba wun won, koda ki oko yen lowo ju sekere lo, ko wa so fun won wipe ki awon omo yi duro
sile, pe won ko gbodo jade, hmm, wahala ni yen ayafi ti ko ba wun awon obinrin abe irawo yi lati
jade nikan lokun.
Ninu ideda won, won ki gbarale eni keni lati bere nkan, won ma nro wipe awon to ija ara won gbe,
eyi totun wa je kayefi ibe ni wipe, won ko ki n gba ki eniyan ma pase fun won.
Ti won ba ti file yanda okan won fun okunrin kan, okunrin na ku orire ni yen, tori ti won ba ni awon
yoo se nkan, kosi eni tole yi won pada kuro ninu ipinu na.

ITESIWAJU LORI IRAWO AWON OMO PISCES


Awon omo abe irawo yi lanu pupo lo, oye ori won mu yanyan, ti won ba nko nkan won a ma tete gbo
ye, won ko ki nse onijogbon, ti eniyan ba se oun to dun won kaka ki won binu, won yoo ka mora bie
nipe ko dun won, amo ti won ba ri wipe enina ko dekun iwa buburu owo re, won yoo ma yan ra won
lodi. Won si tun je oniwapele eda, oye ori won na si po pupo afi bi awon omo Sagittarius eyi si ribe
tori planet Jupiter lo ndari irawo ti won na. Orin nbe lara nkan ti eleda won ro mo.
Wonyi wa si ni awon aleebu won: won je eda kan toni iberu pupo lokan. Won si tun ma ni igbekele
ninu eiyan pupo ju, igbamiran won yoo wu iwa bie eni towa nipo ibanuje.
Lati le mu inu awon omo yi dun dada, wonyi ni oun ti won feran julo: won feran ki won ma dawa lai
ba eni kankan soro tabi lati dawa ni awon nikan, won feran orun sisun, won si kundun ifarakora
(romance) dada, iran wiwo lori amo-hun-mo-aworan (Television), lilo si odo lo we tun je oun ti won
nife si julo, ati asiri ikoko.
Awon nkan wonyi ni won korira ti won ko si fi nfe lati ba pade lodo eniyan: gbogbo eda to ba ti nwu
iwa bie ni pe oun nikan loni imo junlo, won a ma korira won ati awon eni ti won ma nse iyapa enu
lori oro meji, tabi titako oro kan fi gbe oro kan (criticized).
Ti won ba tun ri apere oun toti se won ri, inu won yoo tun ma baje si ni lati ri nkan na.
Ni ibere pepe aiye won, won a ma koju awon isoro kankan. Won ma je eni ti o ma lokiki. Won ma
mu omi pupo. Okiki won ma tete n tan latari ise jeje (Gentleness) won, tori won je eda kan ti ko
feran agbaja.
Awon omo yi ni ebun lati ma pase. Kosi bi won ba se nsise lowo, won yoo da ise na duro ni akoko
toba re won, won yoo koko simi na ki won tun to pada si idi ise na. Opolopo ninu won si ma nse
aikobi ara si nkan miran toye ki won sora si. Bia se ni won je olododo to, mbe ninu won tia tun ma se
aisododo nibi oro won nigbamiran.
Opolopo ninu won ma n beru lati se oun ese kan si ikeji (Sin), tori eru ma nba won gidi ti won ba se
iru re, okan won koni simi rara ayafi ti won ba kuro ninu ese (sin) na. Lotito la so wipe o seese fun
awon omo yi lati koju awon isoro lati igba ewe won, sugbon ti aranse Olohun ba fe deba won, ojiji ni

32
ola won yoo si buyo. Iri-ajo lilo je oun kan ti won ma nse dada, won a sima bimo pupo, ayafi eyiti
owo ba nbe ni ara re lokun tabi ki nkan ti kulo irawo won ni akoko ti won ba bi won.
Larin omo ogun odun si okanlelogun (20-21), ire a ma wole wa fun won.
Ki won sora larin awon odun yi lati dawole nkan tabi lati rin irin ajo, tabi lati kowo le ise kan, tori ki
nsaba si aridaju wipe won yoo yorire sibi ire:
8, 13, 36, 48
Nkan ire yoo ma sele larin awon odun yi, yoo si dara lati mu ninu odun yi lati se oun ti won ba fe se
tori ore yoo po nibe fun won: 6, 12, 24, 39, 56.

ALAYE LORI BIA SELE BA AWON OKUNRIN WON GBE


Ifarakora (Romance) je oun pataki julo lodo awon omo yi. Won ma gbe igbe aiye won ni yi ti won
yoo ma fi ro aiye lorun, ti won yoo si tun ma ba awon eniyan lo pelu ife otito.
Obinrin toba fe ba awon omo yi gbe fun ojo pipe, o gbodo je obinrin ti ko ni fi igba kan bo ikan ninu.
A mo awon omo yi na fun anu sise ti won setan lati ran enikeni lowo lori isoro kisoro ti awon enina
ba ndoju ko, koda Olohun a tun ma fun won ni iyanda lati ma mo iru nkan ti eiyan fe lokan re, tori na
won a ma si se nkan oun na fun won koto di wipe awon eniyan so jade lati enu won.
Awon na feran alawada eiyan, ti won ba ri obinrin to ba le pawon lerin dada, ibagbepo koni lewu
rara.
Omiran ninu awon omo yi, awon obinrin ti won ba ti bimo ri lo ma saba wun won lati fe. Ki won si
kiyesi si arin yi, tori won ma ntete wo inu agbami ife lo, igbesi aiye ife won yoo ma fe ma daru
lawon aye kan, torina oseese fun won lati ma ba ijakule pade lodo awon obinrin, atiwipe won a ma
siyan (si iyawo fe) nigbamiran.
Gege bi oko (husband), osese ki awon omo yi ma le ma se eto won lori pipase oun ti aya (wife) won
ba fe.
Wahala ti ma nbe ninu ise asela won ni wipe, won ma nwa ise to rorun amo won ti gbagbe wipe kosi
ise owo kan to rorun lati se.
Amo ti Olohun bati se ije-mu re ni irorun, gbogbo nkan toba ni ni yoo fi te aya re lorun.

ALAYE LORI BIA SELE BA OBINRIN WON GBE


Obinrin won je eda kan tia mo toni iwa daradara lowo, ti awon na si wa ninu alaro jinle eda, won a si
ma gbe oro awon elomiran si okan won ju eto aye ti won lo.
Tia ba ri okunrin tofe ba awon omo abe yi gbe papo, okunrin na gbodo je eni to nifesi ifararora
(Romance) dada, to si tun je eda to le pani lerin gege bi awon alawada. Paapa julo yoo si tun je
olutetisi si oro arabirin na.
Ni kete ti awon obinrin yi bati fi okan won fun okunrin kan, hmm gbogbo ara won ni won yoo dale
okunrin na, tokan tokan si ni ife won.
Wiwa papo pelu awon omo yi lori ibusun ki nse nkan to ma su ni.
Nigbati awon omo yi ba fema jiroro lori oro kan tabi meji pelu elomiran, won feran ijiroro lori oun ti
nsele ninu aiye yi, won a si tun nifesi ka ma soro nipa awon emi airi tabi nipa ijinle agbara kan,
paapajulo asiri ikoko, oseese ki idi won diedie ma waye nigbati awon ati oko won ba sese wa gege bi
afesona, tori won ni fe koko gba boro lati fe won.
Amo toba ri okunrin toni otito inu to si tun je enikan ti ma so gbogbo oro re fun awon obinrin abe
irawo yi, ife arakunrin na yoo tete wo awon omo yi lara.
Okan awon obinrin yi na le debi wipe, won ko ki ntete gbagbe oro tabi tete fori jin ni, tia ba ri ninu

33
awon omo yi ti okunrin kan ti fun ni ijakule ri lori oro ife, osese ki iru obinrin be pe lati loko tabi lati
tun tete gba fun okunrin toba wa ba won fun oro ife.
Awon omo yi ma ni ifarada lodo oko won, boya won ri oun ti won nwa tabi won ko ri oun ti won wa,
amo oun ti won nilo julo ni suuru ati aanu, atiwipe ti won ba tun ri olutoju rere won yoo ba won pe
titi.
Asiri ife won ni ifararora (Romance), tori ifararora lodo awon omo yi da gege bi eemi (breath) isemi
ara re ni.

ALAYE LORI BI ORIGUN MERIN AIYE SE SO PO MO AWON IRAWO TA NI

Lotito ni origun merin aye ni nbe:


ILA-OORUN (EAST)
IWO-OORUN (WEST)
GUSU (SOUTH)
ARIWA (NORTH)
Bi origun merin aye sewa wa yi, oloju ibiti irawo kankan le gbe ti won si ma nfara mo lati gbe, ni yi
ti yoo si ma se anfani fun iru eni to ba nlo irawo na.

1. ILA-OORU (EAST): ila-oorun je origun ti awon irawo ina ma nferan lati gbe, tosi je wipe ore nla
ma wa fun iru awon eni ti nlo irawo yi, awon irawo nani:
 Aries irawo ina
 Leo irawo ina
 Sagittarius irawo ina.
Awon irawo yi je awon irawo ti ibugbe re wa ni Apa Ila-Orun eyi ti ede geesi re je East, awon omo ti
won ba nlo awon irawo ina tia so si oke yi, ni igbakugba ti won ba fe rin irin-ajo tabi fe wa ise losi ilu
kan ti kosi ni si kaabamo nibe, Ninu gbogbo ilu toba fe lo, afi koya je Apa Ila-Orun (Eastern side)
ilu/orile ede nani ki enina tedo si. Fun apere:
 Gbogbo Ilu ti nbe ni Ila-Orun ti Nigeria.
 Gbogbo Ilu ti nbe ni Ila-Orun ti ilu America.
 Gogbo Ilu ti nbe ni Ila-Orun ti Ilu London
Ati beebe lo.
Ni afikun:
 Irawo Aries tia mosi irawo na, yoo tun ma gbe awon ilu ti orun ma nposi ju, awon ilu to ma
gbona ti ojo ki nfibe ro dada nibe, irawo yi tun ma ngbe ori oke, inu igbo ati inu abule.
 Irawo leo oun feran koma gbe ninu iho-ile, ori oke, inu aginju, inu igbo, ati ilu ti apata ba
posi ju (abeokuta fun apeere).
 Sagittarius, oun feran koma gbe ni Ile ti won ba ti njagun dada ati inu igbo.
2. IWO-OORU (WEST): Iwo-oorun je origun ti awa awon irawo afefe ma nferan lati gbe tosi je
wipe ore nla ma wa fun iru awon eni ti nlo irawo yi, awon irawo nani:
 Gemini irawo afefe
 Libra irawo afefe
 Aquarius irawo afefe.
Awon irawo yi je awon irawo ti ibugbe re wa ni Apa iwo-Orun eyi ti ede geesi re je West, awon omo
ti won ba nlo awon irawo afefe tia so si oke yi, ni igbakugba ti won ba fe rin irin-ajo tabi fe wa ise

34
losi ilu kan ti won kosi ni si kaabamo nibe, Ninu gbogbo ilu toba fe lo, afi koya je Apa Iwo-Orun
(Western side) ilu/orile ede nani ki enina tedo si. Fun apere:
 Gbogbo Ilu ti nbe ni iwo-Orun ti Nigeria.
 Gbogbo Ilu ti nbe ni iwo-Orun ti ilu America.
 Gogbo Ilu ti nbe ni Iwo-Orun ti Ilu London
Ati beebe lo.
Ni afikun:
Irawo Gemini yoo feran lati ma gbe: Inu ogba (garden), ile ayo tita tabi kani tete tita, won wa lara
irawo ti ma ngbe inu yara ti awon eiyan sun si (bed room), ati yara ti won ma nlo fun ayeye (hall).
 Tia ba ri olowo tofe fi owo re se nkan tabi fi de nkan mole, ki iru enibe mu lara awon nkan
tia kasi oke yi, tori ibe ni ire Gemini feran lati ma gbe.
 Irawo Libra yoo feran lati ma gbe: ni ile-ise ti won ba ti sise owo dada (Business).
 Irawo Aquarius yoo feran lati ma gbe ni: Nibi ti awon asiri ba pamo si, tabi awujo ti won ba
ti ma nsoro asiri ikoko, won feran ki won ma gbe abule, Irawo yi na ma ngbe ile ayo
(Gambling).
3. GUSU (SOUTH): Gusu je origun ti awa awon irawo erupe ma nferan lati gbe tosi je wipe ore nla
ma wa fun iru awon eni ti nlo irawo yi, awon irawo nani:
 Taurus irawo erupe
 Virgo irawo erupe
 Capricorn irawo erupe.
Awon irawo yi je awon irawo ti ibugbe re wa ni Apa Gusu orilede, eyi ti ede geesi re je south, awon
omo ti won ba nlo awon irawo erupe tia so si oke yi, ni igbakugba ti won ba fe rin irin-ajo tabi fe wa
ise losi ilu kan ti won kosi ni si kaabamo nibe, Ninu gbogbo ilu toba fe lo, afi koya je iha Gusu
(Soutern side) ilu/orile ede nani ki enina tedo si. Fun apere:
 Gbogbo Ilu ti nbe ni iha Gusu ti Nigeria.
 Gbogbo Ilu ti nbe ni iha Gusu ti ilu America.
 Gogbo Ilu ti nbe ni iha Gusu ti Ilu London
Ati beebe lo.
Ni afikun:
 Irawo Taurus Yoo feran lati ma gbe: ibi ti awon ba ti sin awon malu dada bi odo awon fulani
ti nda malu, ati agbegbe ti won ba ti ma nse nkan ogbin dada. Awon ti nlo irawo yi le mu
awon nkan wonyi gege bi ise, tori ere nla nbe nibe fun won nibe dada.
 Irawo Virgo yoo feran lati ma gbe: inu sobu ti won ba ti sise tabi won ta oja ni sobu na, won
si tun feran lati ma gbe ilu.
 Irawo Capricorn yoo feran lati ma gbe ni agbegbe ti omi ba wa dada.
4. ARIWA (NORTH): Iha Ariwa je origun ti awa awon irawo omi ma nferan lati gbe tosi je wipe ore
nla ma wa fun iru awon eni ti nlo irawo yi, awon irawo nani:
 Cancer irawo omi
 Scorpio irawo omi
 Pisces irawo omi.
Awon irawo yi je awon irawo ti ibugbe re wa ni Apa Ariwa orilede eyi ti ede geesi re je North, awon
omo ti won ba nlo awon irawo omi tia so si oke yi, ni igbakugba ti won ba fe rin irin-ajo tabi fe wa
ise losi ilu kan ti won kosi ni si kaabamo nibe, Ninu gbogbo ilu toba fe lo, afi koya je iha Ariwa
(Northern side) ilu/orile ede nani ki enina tedo si. Fun apere:

35
 Gbogbo Ilu ti nbe ni iha Ariwa ti Nigeria.
 Gbogbo Ilu ti nbe ni iha Ariwa ti ilu America.
 Gogbo Ilu ti nbe ni iha Ariwa ti Ilu London
Ati beebe lo.
Ni Afikun:
 Irawo cancer yoo feran lati ma gbe ni agbegbe omi, ati agbegbe ti won ba nse nkan ogbin
nibe, gege bi irawo Taurus.
 Irawo Scorpio yoo feran lati ma gbe ninu iho ile, ati ori oke, papa julo awon ile ti won ma
nko si abe ile (Underground), won si tun feran abule na.
 Irawo Pisces yoo feran lati ma gbe ni agbegbe ti omi posi ju.

36
TABILI BIA
SE NWO
AWON
IRAWO TO
BARA WON
MU LATI FE
ARA WON
37
EYI NIA MO SI TABILI IFE TIA FI NMO IRU IRAWO TO BARA WON MU LATI FE:

Ari Taur Gem Can Leo Virg Libr Sco Sag Cap Aqu Pisc
Ari 0 1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11
Tau 1 0 1 2 3 4 5 6 7 8 9 10
Gem 2 1 0 1 2 3 4 5 6 7 8 9
Can 3 2 1 0 1 2 3 4 5 6 7 8
Leo 4 3 2 1 0 1 2 3 4 5 6 7
Vir 5 4 3 2 1 0 1 2 3 4 5 6
Lib 6 5 4 3 2 1 0 1 2 3 4 5
Sco 7 6 5 4 3 2 1 0 1 2 3 4
Sag 8 7 6 5 4 3 2 1 0 1 2 3
Cap 9 8 7 6 5 4 3 2 1 0 1 2
Aqu 10 9 8 7 6 5 4 3 2 1 0 1
Pis 11 10 9 8 7 6 5 4 3 2 1 0

ITUNMO AWON NUMBER YI NBE NINU IWE AKOKO TIA PE ORUKO RE NI TAA NI
MI ????, NI OJU IWE 56.

38
EYI NI TABILI TIA FI NMO, IRU MALAIKA TO NDARI OJO KANKAN TO WA NINU
OSE ATI IRU MALAIKA TOUN DARI OJO TIA WAYE TI NSE MALAIKA WA.

PLANETS OJO INU OSE ISLAM CHRISTIANITY


Sun Sunday Malaika Mikailu Angel Michael
Moon Monday Malaika Jabirailu Angel Gabriel
Mars Tuesday Malaika Samosamoilu Angel samuel
Mercury Wednesday Malaika Israfilu Angel Raphel
Jupiter Thursday Malaika Sorifayailu Angel Sachiel
Venus Friday Malaika Aniyailu Angel Anael
Saturn Saturday Malaika Kasifayailu Angel Cassiel

EYI NI TABILI LATI MO IRU MALAIKA/ANGEL TO NDARI IRAWO AWA EDA.

ORUKO AWON IRAWO AWA EDA ORUKO MALAIKA TO NDARI IRAWO NA


ARIES (IRAWO INA) Malaika Samosamoilu/Angel Samuel
TAURUS (IRAWO ERUPE) Malaika Aniyailu/Angel Aneal
GEMINI (IRAWO AFEFE) Malaika Israfilu/Angel Raphel
CANCER (IRAWO OMI) Malaika Jabirailu/Angel Gabriel
LEO (IRAWO INA) Malaika Mikailu/Angel Michael
VIRGO (IRAWO ERUPE) Malaika Israfilu/Angel Raphel
LIBRA (IRAWO AFEFE) Malaika Aniyailu/ Angel Aneal
SCORPIO (IRAWO OMI) Malaika Samosamoilu/Angel Samuel
SAGITTARIUS (IRAWO INA) Malaika Sorifayailu/Angel Sachiel
CAPRICORN (IRAWO ERUPE) Malaika Kasafayailu/Angel Cassiel
AQUARIUS (IRAWO AFEFE) Malaika Kasafayailu/Angel Cassiel
PISCES (IRAWO OMI) Malaika Sorifayailu/Sachiel

39
EYI NI TABILI LATI MO IRU AISAN TI YOO MA WA LARA IRAWO KANKAN

IRAWO IRU AISAN TI YOO MA SE WON ATI IRU JAMBA TI YOO MA FE


KULO WON
Aries irawo ina Iru awon won yi ni yoo ma sele si awon omo yi: Aairi orun sun, ori fifo,
iba, apa lori tabi ni oju won, oju didun (oju won ki nsaaba riran dada ni
ale), Ijamba latara ina jijo, irore (pimple), arun ibalopo.
Taurus irawo erupe Onafun didun, oju fifo,eti riro, segede, orikerike ara didun, eyi ti ko ba
sora yo san ara a sanju latara apoju ora ara won.
Gemini Irawo afefe Aisan latara eegun apa, ejika riro, iko-eefe (Asthma), iko, otutu,aya
didun, kata (catarrh), lakuregbe (Rheumatism), akilolo.
Cancer irawo omi Eje riru. Inu didun, ikifu (indigestion), ogbe inu, igbaya didun, won ki
siso dada.
Leo irawo ina Aisan okan didun, iba, aisan eje ara, igbe gbuuru (Diarrhoea),
atogbe/Atosi, won je omo kan to ma ndaku sere, eyin didun (backache),
oju didun, oyi oju, inu rirun, opa eyin.
Virgo Irawo Erupe Erikerike ara riro, atoka (Appendix), aikundun ounje (loss of appetite),
aisan inu ifun loun (bowel problem), aisan onigbameji (cholera),
airigbeya (constipation), eti didun/ aditi, ifowo bara eni sere ti ato yoo fi
jade (Masturbation).
Libra irawo afefe Arun kindinrin, arun apooto (bladder), atogbe, arun awo ara (skin),
aipeye (impotency), ibaradi didun.
Scorpoi irawo omi Aisan latara oti amu para, eyin riro, aisan koropon, obinrin yoo ma ri
inira toba nse nkan osu (Menstrual problem), ipake (rupture), airi ito to
dada, ogbe-inu.
Sagittarius irawo ina Ori pipa, won a ma saba fi won ati itan won sese, edo didun, Typhoid,
eegun ikoko-idi didun, arun egba (Paralysis),
Capricorn irawo erupe Arun egun ara, ironu, orunkun didun, ete (leprosy), eyin itan riro, eyin
didun (Toothache).
Aquarius irawo afefe Oju didun, isese nibi ese won mo kokose, kokose wiwu, aisa latara ki
eje ma to ara ka dada, eegun eyin, paja-paja (cramps).
Pisces Irawo omi Arun oti mumu, ewo (boils), omo ika ese wiwu, otutu, (ki won sora lati
ma jade nigba ti a ba wa ni akoko otutu, aisan nla ma nkolu won ni
akoko yi), ki won kiyesi awon ogun ti ko bawon lara mu ni lilo, ode ori.

Mo be Olohun ninu ola nla re, ko sowa nibi awon aisan wonyi, ki awa na si kiyesi ara wa nipa awon
aisan won yi, kia moju to ara wa, awon ti a ko wipe won yoo ma ko aisan latara oti mimu, ki won
sora won gidi nibi a mu oti tabi ki won tie jina si oti papa, tori aisan nla lo ma je fun won ti won ko
ti won ko gbo.

40
ASIRI TO PAMO SINU ONKAN OJO TI WON BIWA SAYE
Awon nkan nani:
1,2,3,4,5,6,7,8,9,10,11,12,13,14,15,16,17,18,19,20,21,22,23,24,25,26,27,28,29,30,31
Nkan pamo lotito amo itunmo re nbe lodo awon onimimo, niyi ti afi nse anu fun awon omo araye lati
yo rawa kuro ninu okunkun aiye.
Eyi ni awon asiri to pamo sinu onka ojo tia waye gangan, tosi je wipe opolopo eniyan ni ko kobi ara
si awon oro yi latari wipe komo ibi ti oro na ti nwa, koda elomiran yoo ma se oun ti ko ba onka ojo
tia bi saye mu, eyi sima nfa opolopo isoro sinu aye eni na.
Eyi ni yoo mumi salaye oro awon omo tia bi ni onkan ojo kankan.
Ipele keji, wo Alifabeti to bere oruko re, kio si wo itunmore, yoo so pupo ninu isemi aiye re:
A, J ati S abe onka 1 ni won wa
B, K ati T abe onka 2 ni won wa
C, L ati U abe onka 3 ni won wa
D, M ati V abe onka 4 ni won wa
E, N ati W abe onka 5 ni won wa
F, O ati X abe onka 6 ni won wa
G, P ati Y abe onka 7 ni won wa
H, Q ati Z abe onka 8 ni won wa
I ati R abe onka 9 ni won wa.
Fun apere omo ta so ni Abiola, tia ba lo wo alifabeti to bere oruko re ao ri wipe 1 ni, leyin tia ti ri yi,
ao lo ka oro tia kosi abe onka okan (1), oro na yoo si lapa lara omo na.
Ipele keta: Tia ba se isoro oruko ati oro idile wa papo esi to ba fun wa yoo lapa ninu isemi aiye wa na,
fun apere.
ADEBAYO= Oruko Idile, TIJANI=Oruko ti won so omo na
A= 1
D=4
E=5
B=2
A=1
Y=7
O=6

T=2
I=9
J=1
A=1
N=5
I=9
Apopo oruko molebi ati oruko omo yi yo wa je: 1+4+5+2+1+7+6+2+9+1+1+5+9=53, oruko na fun
wa ni 53, tia ba ri iru onka yi, oti di dandan kia ro onka na papo ti yoo fi fun wa ni oun ta fe, fun idi
eyi ao wa tesi waju bayi wipe:5+3=8, esi ejo (8) tia ri yi oun la wa lo ka oun ti nbe ni abe re, osi ti di
dandan ki onka na lapa lara omo na.
Amo awon onka meji kan be ti kose dinkun bee nani kose yo kuro, onka nani: 11 ati 22, awon onka
meji won kose dinkun beesini won kose yo kuro.

41
Se onka ojo to waye ko si wo itumore:
16/october/2017: 1+6+1+0+2+0+1+7=18=1+8=9.
TABILI TIA FI NMO APEPO ORUKO TOBA ONKA OJO TIA WAYE MU
OJO TI OMO WAYE aropo oruko omo na gbodo fun wa ni onka yi

1 1,2,9,3
2 2,1,5
3 3,1,2,9
4 1,6,5
5 5,1,6
6 6,5
7 1,6,2
8 1,5,6
9 9,1,2,3
Apeere bia se nlo omo ti won bi ni ojo akoko (1) tia so ni Sodiq, tia ba se onka oruko na ao ri wipe
won baramu lona wo?
S=1
O=6
D=4
I=9
Q=8
1+6+4+9+8=28=2+8=10=1+0=1.
Tia ba wo ao ri wipe apapo oruko omo na gbe.
Ti won ba tun fi alifabeti miran kun oruko yi, osese ko tako:
Assiddeeku
A=1
S=1
S=1
I=9
D=4
E=5
E=5
K=2
U=3
1+1+1+9+4+5+5+2+3=31=3+1=4.
Tia ba wo aori wipe oruko yi koba onka ojo ti omo na waye sise.
Ikilo: Onka ojo tia bi omo lama mu, ki nse odun ati osu ati:
Omo ti won bini 23 june 1985: Ao wa mu onkan ojo to waye wipe; 2+3=5, fun iru omo yi, apepo
oruko re gbodo fun wa ni: 5 tabi, 1 tabi 6.

42
ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KINI NINU OSU (1ST OF THE
MONTH)
Ipo Olori ni awon omo yi muwa aye. Won si ma ni ipinu rere fun ojo iwaju won, gbogbo ona ni won
si ni won ma nwa lati ri wipe gbogbo erongba won wa si imuse.
Awon omo yi ki ngbara le enikeni, won ma nfe dawa ni, ti won si tun feran ki won ma se nkan won
gege bi ero okan won ti se gbe wa fun won. Idi niyi ti won fi korira lati ma da ise papo pomo enikeni.
Ise tete ma pin awon omo yilemi, nigbati won ba gba ase lati odo enikan tabi ki eniyan ma pawon
lase wipe se nkan bayi, se nkan bayi.

Bi eni iwaju, eni iwaju loma nse awon omo yi, ki won si sora tete ni tita tori o wa lara nkan ti won
feran. Ogbon atinuda nbe lara awon omo na, won si tun je eda kan to jafafa ti ki nfi nkan re fale rara.
Agbara lati dari opo ero nbe lara awon omo yi, bee sini won ni oye lati dipo nla mu nidi ise won.
Won je eda kan ti ki nfi gbogbo oro re sere, won ki saaba dasi oro tabi gbero nkan laije wipe won ni
nkan ti won fe fi oro na se tabi fi ero na se.
Ogbon inu ati imo ijinle je oun pataki ti Olohun fi jinki awon omo yi.
Ireti nla je oun to se pataki ninu ise awon omo yi, ti won si ma nfi oju sun nkan, bi won se ma ni ireti
fun ra won nani won se ma nro oro omo lakeji won pomo ti won na.
Ki awon omo se akiye si ara won nigbati won ba pe omo 28 wo 56, won yoo gbe oun mere mere se
ni arin odun yi.
Yoo dara fun won ti won ba le ma wo oye elomiran mo ise owo won amo iwa agidi inu ati iwa
orikunkun won ni ma jeki won ranri mo ero okan won nikan.
Okan awon omo yi tabi kani opolo awon omo yi ki nfi igba kan sinmi rara, irori ni ni gbogbo igba,
opolo won ma nsise bi ago ti koki sinmi.
Kosi iru ise tabi ijakule ti awon omo yi ba bapade, won ma nro ni okan won wipe awon yoo bori e,
ati wipe isekise tabi isorokisoro ti won ba ba pade, won ma tun ko imo lata re ni.
Akiyesi:
1. Awon omo yi gbodo sora fun ole (laziness) ati kama fi nkan fale (delaying).
2. Lotito awon omo yi je eda kan ti ma nbinu, nkan si ma ntete su won, ti won ba wa nreti nkan, won
a ma kanju lati ri wipe o te won lowo, amo iwa yi ko darato ki won fi suru te.
3. Ipinu won ma nfun won ni agbara ati lati gbe nkan rere se, ki won gbinyanju lati ma tele ipinu won
tori ore nla nbe nibe, ipinu won yi si je okunfa ore nla fun won.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OJO KEJI NINU OSU (2ND OF THE MONTH).
Awon omo tia bi ni ojo onka yi je awon omo ti won ni ifura gidi lara, gbogbo nkan ti awon omo yi ba
nko lomo ntete ye won, opolo won mu dada nibi ka ko eko ti yoo si yeni dada ati wipe won je eda
kan ti won le rin ni ona oselu tori oro oselu ye won dada. Adugbo ti awon omo yi ba ngbe ma lapa
lara won, ti okiki won si ma nkan dada ni ayika ibiti won ba wa. Won feran ki won sa ba ma ri awon
oun to rewa, ni gbakugba ti won ba si nsoro lowo, won a ma fe ki opo eiyan ma tete si oro enu won.
Nigbamiran awon omo yi a ma kosi inu ironu, ti ironu yoo si gba okan so, eyi a si ma fa akoba fun
igboya won, tori ni akoko ti okan won ba gbogbe ko ki n si igboya fun lori oun ti won ba fe se ni
akoko (Time) na.
Ebun ti Olohun fun awon omo yi je ebun tonise pelu ifomoniyan se ati oro oselu, nitori Olohun a
saaba ma fi ero okan awon eniyan han awon omo yi, tosi je pe oun sini yoo ma fa okunfa bi awon na
yoo se ma yanju awon awo (dispute) to ba wa larin awon eniyan ti irepo yoo joba ni agbagbe na tori

43
wipe yoo mo ero okan awon eniyan re ati ero okan awon ara ilu re.
Awon omo yi le rin ni ona oselu, tori gbogbo igba ni won a ma wa ona aseyori si oun ti o ba ndun
awon eniyan ti won ba mo ri. Opolopo ninu awon omo yi na yoo ma ni ebun si orin kiko. Won je eda
ti ara won bale pupo ti won si je eni ti ma nife awon eiyan tosi je wipe awon na ma nreti ki awon na
ri ife lati odo ore to sunmo won dada ati lati odo alabagbe won, gege bi awon tise ma nfi ife han si
araye.
Osese koje wipe ore ati igba ewe won ni won yoo fe. Opolopo igba ni won si ma nfe ki awon wa
gege bi eni ti yoo wa ni idaabo bo.
Won je eda kan to nife afowosowopo ti so je wipe yoo ma dara fun nigbati won ba se ise ni ajosepo
pelu awon eniyan re, won feran ki awon ma je alatileyin fun awon eniyan ju ki won ma je asoju lo.
Won ma mo ero okan eniyan koda ki eni na to so fun won. Won je eda to le yori ise sibi rere ju ki
won se ise na lati ibere lo (Ki won ma kun eniyan lowo sise lodara fun won ju ki won ni awon yoo
sese beere todo won laye oto).
Agbegbe toye awon omo yi lati ma gbe ni, agbegbe ti won ba ma nfi han dada ti won si ma ngbe ni
ayo ati alaafia ti ki nsi ariwo nibe. Lairi awon omo yi adugbo kan, adugbo na ki nsaaba dun dada.

Akiyesi:
Pelu gbogbo iwa daradara tia ka sile wipe awon omo yi ni yi, osese ki awon eniyan mafi san esan
aburu fun won, ti kosi si aridaju wipe won yoo ri ore gba lati odo awon eniyan gege bi awon se feran
ki won sore fun eniyan.

Lotito nia so wipe awon omo yi dangajia ninu oro oselu amo, ki won rora se tori eni tia ba na owo ife
si nigba miran yoo ma fi ibi san fun ni pada.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OJO KETA NINU OSU (3RD OF THE MONTH)
Awon omo yi ni imo bia tise nfi nkan dara, tabi kia ma ya nkan, ti awon oloyinbo pe ni (Artist). Orire
ni yoo ma je fun awon omo yi ti won ba n rin ni ilana, iwe kiko (Writing), fifi oun ero amayederun fi
si ise bi (Graphics), tabi ki won ma sise ona (arts), ti awon omo yi kobai ti ri ise se tabi ti won koi ti
mo ise ti won fe se, iba dara fun won lati mu ninu ise tia kasi oke yi papa julo awon onise ona tia
mosi (Arts) ni ede geesi.
Olohun jogun opolo pipe fun awon omo yi dada, won si tun je eda kan ti ma nro aro-jinle dada.
Awon omo yi ma ni iminsi lara dada, opolopo nkan ni Olohun ma nfi han awon omo yi, paapajulo
latari ala lila won, won yoo ma ri nkan ti yoo ma sele.
Opo eniyan loma nri awon omo yi gege bi iwuri ati wipe won a ma mu won yangan nita, won a si ma
wun eniyan lati sunmo tabi lati ba gbe (live with someone) tori won ni eran iferan lara dada, ayifi eyi
ti won ba ti kolu.
Won je eniti ti nko ore mora dada, opolopo eniyan losi ma nfe je ore won, hmm, okunrin won yoo
ma wu obinrin lati fe ti opolopo obinrin yoo si ma du won fe, gege be na lori lodo awon obinrin won
ti opolopo okunrin ti yoo ma saati won gege lati fi won se aya.
Nigbamiran won ma sonu ooo, ti won koni fe ba enikeni soro ni akoko na latari boya won ri oun
ibanuje kan tabi omiran.
Awon na mo bia se npe ife si arin awon eniyan, won si tun nife si kia ma to ile leso, niyi yoo ma fi
won han bee na sini won ma nfe mura lati le fa oju awon eniyan mora.
Olohun tun fun won ni ebun bia se nto ohun-igbin ati ododo.

44
Akiyesi:
Ki awon omo yi sora nibi a nfi akoko sofo nidi oun ti ko jamo nkan nkan tabi oun ti kosi ere nibe.
Ki won je eniti yoo gbaju mo ise kan loda ju fun won ju ki won ma bosi yin bosun lo.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KERIN NINU OSU (4TH OF THE MONTH)
Awon omo tia bi ni onka ojo yi je awon omo ti won ki nfi ise oojo won sere rara, won a ma mu ise
won lokunkundun ti won yoo si ma se ni aseyege pelu ijafafa nidi re.
Won je eda kan to ma nfura tosi ma nse akiyesi gidigidi si oro aiye re.
Won je enikan ti ki nfi ona eburu sise re tabi kanju sise, ati wipe won ko ni igbagbo ninu ise abo
(half), tori na ti won ba ti le dawo le ise kan aseyori ise na ni won yoo se ti won so yori re sona to da.
Won ko oro iwosi bee sini won ko nife si awon opuro eda.
Won je eni toni ipinle-oye (principle), won si gbeko dada, won si tun je omo tole soju eni ti won sile
duro fun ni, ni igbati a ko ba si nibe.
Won le je omo toni igberaga oo, amo oo won ki nse oni jagidi-jigan rara.
Won ni anu omo niyan loju. Oseese ki won ma ri awon adojuko bi: idena tabi ijakule, tabi isoro toje
wipe awon nikan ni won yoo mo isoro na.
Awon omo yi feran molebi won dada, sibe won ko ni iwa imotara-eni, tabi mase asehan wipe awon
nife si nkan bayi, tori won ki nfi ife won han sita rara.
Eto bi igbesi aiye awon omo bi yoo se da ni won ma gbaju mo, koda lati igba ewe won ni won yoo ti
ma fi oju sun nkan ti won yoo se ni ojo ola awon omo won. Oro ti awon omo yi ba nso ma saba mu
ogbon wa. Won ki tete je olowo ayafi eyi toba ba owo nile lokun, tori ideda won je ideda ti nkan re
ma n wole, ti won si gbodo fi suru gbe tori ki won ba ma kabamo ni gbenyin.
Alatunto ni awon omo yi ma nya ti won si tun je olusakoso (Manager) rere.
Opolopo awon eniyan lo ma gbara le awon omo yi, paapa julo awon molebi won ati awon ti won ba
nba sise. Tori won ma ri awon omo yi gege bi igi leyin ogba ni tose gbara le.
Akiyesi:
Awon omo yi le buru die oo, ti won si ki nfe gba imoran booro, ideda won ni lati se suru ni opolopo
ona, tori ti won koba sora eyi le mu ki gbogbo iwa ire owo won soju dele.
Won gbodo je eni ti yoo ma gba imoran, lotito osese ki won ma ri atako lodo awon eniyan tabi
ifiya-jeyan, won ko gbodo wo nkan won yi fi si iwa wu, ti won ba sebe eyi le mu won di ailoye
niwaju awon eniyan.
Ki won sora fun ise aseju.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJOKARUN OSU (5Th of the Month).
Awon omo tia bi ni ojo yi feran iyipada kuro lati ibi kan sibi kan, won feran irin-ajo lilo pupo, ti idi
won kosi ki nduro si ibi kan.
Ile-aye loju awon omo yi dabi adugbo loju won ni, idi re re ti won fi feran lati kaakiri lati ibikan sibi,
tori won yoo ma ro lokan wipe awon le rin aye ja, eyi si ribe tori won ma wa awon oun ti nbe ninu
aiye.
Ninu ka ni afarada awon omo tia bini ojo yi je okan lara won, won a ma ni afarada lori gbogbo
ipokipo ti won ba bara won. Won je omo tonilo idunu pupo.
Ibagbepo won pelu awon eniyan ma nje ibagbepo to dan moran, tio si ni si wahala, koda won ni
opolopo ebun agbega ninu aiye won, oludari rere ni won, awon na nbe lara awon ti Olohun jogun
oun kiko (Writter) fun.

45
Awon omo yi feran oro siso dada, latari oro siso won yi lo fi mu ki won je eda tole ta oja dada.
Iba sisepo pelu awon elomiran tabi idowopo pelu elomiran ma n ja si irorun fun awon omo niwonba
igba ti ko ba ti si ihamo tabi ifaseyin lenu ise na.
Ise lilo bibo lo ye awon omo yi, ise kama duro sibi kan, tabi lai laikuro nidi ise kan, ko ye awon omo
yi. Ti won ba se eyi, o le fa ki won ri ewu nibe tabi ki awon olusise ni ile ise paro oun ti won ko se mo
won, ayafi ti won ba kuro lati ibi kan bosi ibikan lo ya kun.
Nigbamiran awon omo yi ki nfe simi, gbogbo igba bi ki won ma sise lo ma nse won.
Won le je eni ti akole fi okan tan nigbamiran, eyi ma nsele nigbati a ba ni ki won da di ipo kan mu,
fun idi eyi won ni lati lo ko bia se gboran ati isera-eni (discipline).
Awon omo yi ni okan to mu yanyan ati oju inu lati wo awofini nkan lokan. Ogbon agbonju ma nje
isoro awon omo yi ati orikunkun nigbamiran.
Ogbon iwoye si oro ti Olohun jogun fun awon omo yi, oun lo ma nfun won ni agbara lati le wa
ona-abayo si oro won ati oro awon elomiran to sun mo won nigbati won ba wa ni inu isoro kan tabi
meji.
Akiyesi:
1. Awon omo yi le je alaini suru omo ti won yoo si ma fi ibinu kun oro won nigbamiran. Jowo loko
bia ti se ni suru lori nkan ki kan to ba da e.
2. Awon omo yi feran awon nkan wonyi ni afe ju: ounje jije ajeju ni won ma nje, oti mimu amuju ni
won ma nmu, ibalopo, won kun dun re pupo debi wipe ti oko won tabi aya won koba le te won lorun,
won yoo ma wo ita, ti won ba si feran ogun afeju ni won ma nfe (Woye si eyi to je tire nibe, kio si so
ara re dada nipa re, tori apo nkan, aburu ni ma ndale).
3. Lotito la so wipe iyipada (change) kuro lati ibikan bosi ibomiran lo se koko fun awon omo yi, ti
iyipada yi yoo si ma de ba gbogbo oun ti won ba nse laye atiwipe awon na yoo lo anfani yi lati ma
kuro lori nkan bosi nkan.(ki won gbinyanju lati ma lo ebun yi lona to peye).
4. Ti won ba gbero lati reti wipe iyipada rere ni yoo ma da ba won, eyi le fa ki idaduro de ba won,
tori obiri laiye toba yisi iwaju oti di dandan ko tun yi seyin.
5. Ere ori itage, iwe kiko, oro siso, oja tita je adamo awon omo yi.
6. Won ni ogbon lori lati se idajo larin awon eniyan to ba nja tabi lati yori nkan larin eniyan, won tun
je alawada omo.(Gbinyanju lati lo awon nkan wonyi si ona ire).

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KEFA OSU (6TH OF THE MONTH).
Awon omo yi je eda kan ti Olohun bun ni ebun lati ma dasi oro molebi, ti Olohun si tun gba won laye
lati ma pari aawo (disputes) larin eniyan meji to si jasi wipe ejo ti won ba da larin awon mejeji yi, ejo
na koni fi si apa kan ju apa kan lo.
Ise akoko tia ran awon omo yi wa se laye ni wipe ki won wa se ni iwotunwonsi (Balance) larin nkan
meji tabi larin onija meji.
Awon omo yi ni lati ma lo awon oye agba lati fi gbe ile aiye latari awon eniyan ti yoo ma wa ba won
fun iranlowo, ejo dida, ise sise, owo yiya, ti won si gbodo dojuko nkan eyokan ti won yoo mu lati ma
fi ran omo araye lowo, paapa julo oro idajo.
Oro elekeji ni wipe, idojuko (focus) won tun ma saaba lo sori ibatan (relationship). Won a ma feran
lati ma ran yan lowo, Olohun si tun ma nyanda emi Oluwosan fun won, tori re ni won fi ni anfani lati
wo ni san, boya lokan tami onamiran, amo apeere to foju han ni ise Dokita (Doctor).
Ki awon omo yi lo mo daju wipe gbogbo oun ti won ba se ni awon eniyan ma yin won koda ti won
ko ba yin won niwaju won, dandan ni fun eni ti won se ore fun lati yin won leyin won.

46
Itako tun ma nje oun ibanuje nla fun awon omo yi, nigbakugba ti won ba ri atako, inu ironu nla ni
won ma nwa.
Akiyesi:
1.Ki awon omo yi kiyesi ona ti won ba tun gba fi ran ni lowo, ki won mojuto ona na dada tori ere-je
nla ni yoo ma ti be wole wa fun won.
2. Ki won moju to ebi won na dada, ati wipe won je eni ti yoo ko ipa topo ninu molebi won.
3. Won kosi gbodo ko ore ni sise, gbogbo eni toba wa iranlowo wa si odo won ni ki won se fun.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OKO KEJE NINU OSU (7Th of the Month).
Awon omo tia bi yi ma onka ojo yi won a ma tete ro nkan lokan won. Oun to je pataki ninu awon oun
ti won wa sele laye ni lati se iwadi dada nipa oun ti nje aye (world) ati awon oun to kosi nu. Eleko ni
won, awon na wa ninu eni ti Olohun ma nfi emi itona mo.
Won ni anfani lati koni ni eko won ni ona ti yoo mu ire wa ba awon na.
Ebun ogbon-inu/ohnmo tun nbe fun awon omo yi, won si gbodo se ara won jina dada nipa sise
aajo/awe gbigba, adura sise, tabi nipa wiwa agbara lati file ri ogbon inu won yen lo fun omo ara ye,
ati lati le koju awon isoro ti won ba ndoju ko.
Ni kete ti won ba ti gba oun ti okan won ba nso fun won gbo, igbagbo won yoo ma rinle lori gbogbo
ero okan won.
Ki won sora won gidi nibi ifa (gain) tabi ere to ju oun ti won nwa lo, ki won si sora nibi ima fi eru
gba ibunkun. Ki won si sora fun tete tita. Tori ideda won ko ro mo kama fi owo kekere gba nla, aije
be! gbogbo ero ibi towa nidi nkan ti won se yen ni yoo ma yi le won lori ni oju-ese. Awon omo yi ma
nferan ki won ma da sise won lai pe enikeni.
Won a si ma fe ma tete yanju ise ti won da wole ki won si pari re lekan na.
Igbamiran won ma nfi oro won tabi edun okan won pamo lai so fun enikankan tabi lati so mo oro fun
elomiran.
Won ma nfe wa ni awon nikan gege bi ki eniyan ma da wa, amo won ni lati sora nipa iwa yi, ki awon
eniyan malo ma fi nkan miran ti sibi oro na, tabi ki awon eniyan ma pawon ti si bi kan ni apati lai ta
si.
Awon omo yi na je olokanlile, ti won si ni agidi inu.
Won gbodo so iwa yi, ati iwa ailanu loju, ati lati ma se iwadi ofin toto.
Iwa ahun nini ti nbe lara won, yoo ma fa ibanuje na fun awon omo yi, won a si tun ma koju ibanuje
ninu igbayewo won nigbati won ba ti feran won sile tan, won si gbodo sora gidigidi.
Ona abayo: Ti won ba se igbeyawo ki won towo gbogbo buburu awon won bole, aijebe ibanuje ni
yoo fi gbe ile re.
Akiyesi:
1. Awon omo yi gbodo lo ko bi won yoo se ma so ero okan won fun eni ti won sun mo dada ati eni ti
won fi okan tan.
2. Ki won si lo ko bia ti ngbe pelu eiyan, ki won lo ti iwa baba ndagbe ati iwa iya ndagba bole.
3. Ti won ba nse awon nkan won yi, aiye won yoo ni itunmo.

AWON OMO TIA BI NI OJO KEJO OSU (8TH OF THE MONTH)


Awon omo yi ni ebun adamo lati se ise owo sise, awon omo yi si dangajia nipa kia wa ona lati ko
owo jo. Awon omo tia bini ojo yi ni imo bi won se dajo larin awon eniyan tabi lati ma yanju oro,
opolopo igba si ni won ma ko ejo wa si odo awon omo yi lati bawon yanju oro na, nitori awon

47
eniyan ma ngbagbo ninu idajo won wipe idajo won je idajo ododo, fun idi eyi ni gbogbo ibikibi ti
awon omo yi ba wa, Olori ni won ma saabe je.
Amoran nla fun awon omo yi:
Gbogbo ipokipo tabi ayekaye abi ni bi ise won ati ni gbogbo ibikibi ti awon omo yi bati bara won, ki
won sora nibi kia won ma dasepo pelu elomiran, eleda won ko ro mo ki won dase po pelu elomiran
tabi enikeni, ti won ba se eyi o le fa ki ifaseyin waye nibi ise ti won pe eniyan si yen.
Oun nla towa wa pelu awon omo na ni wipe, ayekaye ti won ba wa, opolopo igba ni won yoo ma ri
eniti yoo ma ba won se idije lori nkan ti won ba nse, bee sini awon eniyan ma nfe bawon dowo po.
Amo ki won sora ni arin yi tori iseda won ko romo lati dase po pelu enikankan, ki won ba ma
kabamo nibi idowopo na tabi ifaseyin.(Won kogbodo fi asiri ola won han enikeni).
Ki won ma mikan rara tabi se iye meji nibi oro yi, tori won dangajia nidi ise won.
Ninu ebun ti Olohun tun fun awon omo yi nipe won ni agbara lati dari opo ero, tabi kani apopo
eniyan, fun idi eyi ikilo miran re fun awon omo na, ikapa nbe fun won lati dari ise won, eyi to ba si
ndase re papo pomo elomiran kolo jawo nibe, ko ma se asoju ise na fun rare tori nbe ninu kadara re.
Ipo adari ni ipo awon omo yi lorile aiye, eyi lotun fi rorun fun won lati le ko opo eniyan jo, ti won
yoo si ma dari awon eni ti nbe labe won lai ni si wahala kankan. Ni awujo ti awon omo yi bawa
opolopo eniyan lo ma nfe gbo oro enu won tabi idajo won, tori won gba wipe otito ni idajo won. Ni
opolopo igba ni awon eniyan ma nwa iranlowo lo si odo awon omo yi, bee na sini awon eniyan ma
saba gbe arale awon omo yi.
Awon omo tia bini ojo feran ipenija (challenge), idi niyi tofi je wipe kosi nkankikan ti won ba ma ba
pade ti yoo wa je tuntun siwon rara! Tori gbogbo igba ni won ma ngbaradi fun ipenija. koda ti awon
omo yi ba nreti ore lati ibikan, okan won yoo si ma so fun won wipe, ipenija yoo wa ki ore na to te
won lowo, bee sini kosi iye meji nibe ipenija na yoo so waye. Awon omo yi feran ki won ma fi owo
ti won ba ni han saraye.
Ti awon omo yi ba ni owo lowo tan, tabi ki won ri ere nla je nibi okowo won, won yoo ma fi ore na
han latara ki won ma kole nla,rira oko bogini, rira oun meremere ti eniyan yoo fi mo wipe lagbaji ni
owo lowo. Won je edekan to feran molebi re won, ki nfi molebi won sere rara.
Awon omo yi ni ise to le, ipanle diedie si nbe ninu iwa won, won si tun ma nfe je oga.
Nipa kia ni suru, suru die ni awon omo yi ni, suru ara won ko po rara. Opo igba ni awon omo yi ki nfi
edun okan won han sita.
Olokiki omo ni won.
Akiyesi:
1.Awon omo yi ni lati sora nibi kama ni ero aburu lori nkan, tabi kama reti ipenija lori orikan, tori
oun ti won ba nro ni yoo ma sele si won.

2. Won yoo koju opolopo isoro ninu igbesi aye won, amo won ko gbodo baraje, won si gbodo ni suru,
tori ipenija lasan loje fun won, awon isoro ti won ba si nkoju yi, ni yoo mu igbagbo won rinle, ti
okan won yoo si de lori gbogbo oun ti won ba dawole.

3. Ki won sora nibi an dowo po pelu elomiran, tabi lati ma sise kona. Pataki julo, lekeleke won
kogbodo fi ibi to ti nfo aso re han eyekeye.
Itunmo: Eewo ni fun won lati fi idi ola won han eniyan tori idiwo le waye lati be.

4. Itore anu dowo won, ipokipo ti won ba wa, ki won sanu. (Idi ni wipe opolopo eniyan ni yoo ma

48
reti ore lati odo won).

5. Eewo ni fun awon omo yi lati fi imo ti won ba mo pamo, ti won ba se eyi, imo na koni pe ti yoo fi
fiwon sile.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KESAN OSU (9Th of the Month).
Awon omo tia bi ni onkan ojo yi, ma nfe lati ma je ki gbogbo oun ti won ba fe ma ri saaba ma je oun
titun tabi oun ti ko si ni agbegbe ti won wa, won ma feran nkan okere ju nkan to wa ni ayika won lo,
awon na ni anu loju. Ki awon omo ti won bi ni ojo yi gbinyaju lati kawe, ki won gbiyanju dada lori
eko toni se pelu ise ona (Arts). Tori opolopo awon onise ona (Artist) ni won po labe onka ojo yi.
Awon omo yi ni ipa pupo lati ko ninu egbe ti won ba wa ni yi ti won gbodo tun gbinyanju lori
ifomonihan se ninu awujo na.
Amoran: Awon omo yi gbodo ni opolo pipe lori ise owo won, atiwipe ti Olohun ba wa yanda imo na
fun won tan, oti di ofin fun won lati lo si ona to peye.
Ipenija kan ti nbe fun awon omo yi tabi kani lara oun ti won gbodo se laye won ni wipe: ki won wa
nkankan ti won yoo ma se ti yoo si ma je ore fun awon eniyan, tabi ka pe ni saara.
Bi won ba si se nse ore fun awon eniyan to ni agbega ni yoo se ma ba won ti Olohun yoo si ma mu
won di won ni amure nla.
O ma npe ki awon omo ti won bi ni ojo kesan osu (9th of the month) ki won to yan ise ti won o ma se
gege bi ise ojo won.
Awon omo yi je awon omo ti Olohun fun ni afani bia se to awoju eniyan, awon eniyan feran awon
omo yi dada.
Awon omo yi je eda kan ti won ki nfi oro won pamo. Won nifesi eko ogbon ijinle. Awon omo ti won
wa labe onka yi maa saaba ri owo bi ki won jogun re.

Akiyesi:

1. Awon ti won wa labe onka yi gbodo lo ko bia tise nforijin eniyan.

2. Won gbodo sora iru ore ti won ba ma ni, won kogbodo ba ore ti yoo mu won sina rin.

3. Ki won gbinyanju lati ko eko nipa oun to pamo fun won, won si ni afani lati ko ti ire si ma ti eyin
re yo.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KEWA OSU (10th of the month).(1+0=1)
Awon omo tia bi ni onka ojo yi je awon ti won ma nso wipe gbogbo ona ti awon ba mo ni oun yoo
gba lati fi se orire. Won a si ma fe dawa ni eni ti won ko ni ma pa ase fun ti won yoo si fe wa ni
ominira ara won. Awon omo yi na a ma dara pupo ni ipo olori. Idanwo ti won wa se laye ni wipe ki
won gbe ile-aiye gege bi akunleyan won, ni yi toun tunmo si wipe, won gbodo ni igboya ati imi
(stamina) lati le koju awon idiwo/idena ti yoo ma fe ma ba won ati wipe lati tun le ja fun ominira
won gege bi nkan ti awon na nwa.
Okan awon omo yi mu dada won a ma tete ro nkan won si tun mo bia se nyanana oro.
Won a ma gbe ero ori won kale ni ona to peye ti won si tun ni anfani lati ko opo eniyan jo, lati file
yanju awon nkankan ti won gbe si okan won.

49
Awon ise ti won je wipe o ni ilana tia fi nse won tabi kani oni ipele ti ise na gba, iru ise be ma nsu
awon omo yi.
Awon omo yi ki n saba beru enikeni tabi nkan ki nkan toba doju kowon.
Gbogbo oun toba ndabi ihanmo tabi idena lodo awon omo yi, awon nkan na a maa saba yi si
iranlowo lori dukia won ni tabi kani won yoo tun ma ni alekun dukia lorire.
Ima yanana oun kan toba fe dabi idiwo tabi oun to le (difficult) kan, yoo ma saba ma jasi irorun fun
awon omo yi ni.
Gege bia tia se so ni oke wipe awon omo yi ni anfani lati le je olori, tosi je wipe ni ayakaye ti won ba
ti je ipo olori yi ni won yoo ma ri aponle nla latara awon eniyan.
Ikilo: Ti won ba wa ni ipo nla kan tabi ipo agbara kan, ki won sora lati ma lo ipo na tabi agbara na
lori awon ti won se alatileyin won de ipo ti won wa ati lori oko won tabi iyawo.
Oseese ki iwa yi ma (don't) han ninu iwa won si molebi won, tori molebi won badi eyin lowo won
ni.
Awon omo yi le ni agidi-okan tabi okan lile nigbati won ba ri oro kan ti ko te won lorun, tabi oun kan
ti won fe se ti won ko wa raye se.
Sibesibe olotito ni won, ti won si setan a ti ran awon ore won lowo.
Iwa ibanikegbe tun je oun kan ti nbe lara won, ti won si tun je ojowu pupo lori nkan, papa julo ti won
ba ri eniwon kan toun n se orire tabi ti n ra oun meremere kan, eyi yoo ma sele nigbati won ba nri iru
nkan wonyi lodo ore won tabi lodo akegbe won, tori awon na yoo ma gbero lati se nkan ti eni na se
Akiyesi:
Ki won ma kiyesara nibi erongba won ati ise owo won ki won ba le tete debi ti won nlo.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI TIA BINI OJO KANKANLA OSU (11th of the
Month "Master Number" onka yi kose ropo besini kose dinkun)
Lodo awon onimo onka tia mo si (Numerology), onka 11 yi je oga lara awon oga onka.
Ogbon ori awon omo yi, je ogbon to mu gidi ti won si loye dada. Ninu ogbon ati oye ti Olohun fun
awon omo yi, oun ni o le mu won je Oludamoran tabi olugbani-niyanju ti won si tun ni anfani lati ma
wo awon eniyan san ni ona ti Olohun bani ki won mo. Idi ti won fi ni awon nkan won yi lara ni wipe
opo ninu won lo ma mo ero okan eniyan ki won to so fun, ore (fortune) yoo si ma to won wa larin yi.
Won mo bia ti ko eniyan jo ati bia se ndari won si ona to ye, idi ni yen ti awon na sele wa ni ipo olori,
amo ipo olori ti won yoo wa, iwuwa si won ni awon eniyan yoo ma wo lati file kose ti won, bi won
se ma n se ipo olori ti won re: ti won ba ri enikan to ni isoro kan tabi ni idiwo kan, won yoo gbinyaju
lati la ona ti enina yoo to ti yoo si fi ri ojutu si oro re, ti won ba si ti fi ona na han won tan, won yoo
fi won le lati ma ba oro won lo.
Amo eyi ti okan awon omo yi ba ti file ni awon yoo se ise na pari, kosi oun kan tole di won lowo lati
ma pari ise na, won yoo pari re sibi ire.
Iyara nibi imo awon omo yi ma fe fa ki aiye won fe ruju die si won.
Awon omo yi won a si tun ma se akiyesi si ironu awon elomiran, ibaaje ironu na kan won tabi ko kan
won, won gbodo kiyesi.
Awon omo yi gbodo sise won dada lati le ma fi bori awon isoro keke kan ti yoo fe ma kolu won.
Ti won ba fe wa nidi ise kan, ki won gbiyanju lati di ipo olugbani-nimoran mu.
Ki awon omo yi sora nipa jije ajeju ora (fat) ati suga.
Awon omo yi won ki nsaba ni ota, tori iferan ni onka 11 yi je gbogbo aiye. Awon omo yi tun ni
awon nkan lati mu awon nkan se ti yoo si ma bosi won lowo, niyi ti nkan na le le (difficult) fun awon

50
Number miran lati se.
Won je ariran, Alaala ati wipe gbinle awon emi airi, awon elede geesi a ma so wipe Spiritual.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJOKILA NINU OSU (12th of the Month, 1+2=3).
Awon omo tia bi ni ojo yi, ma nsaaba mu awon nkan wonyi ni pataki si ara won: ile won se pataki si
won, ounje gbigbo, ati bi won yoo se ma fi ara won han si awon eniyan ati bi awon eniyan yoo se ri
iwa won.
Awon omo yi feran ayeye pupo, won si kun dun kia ma lode afefeyeye, won si tun je eda kan to ma
ndani laraya nigbati won ba joko lawuju eiyan, latari siso: itan, sise awada, ati gbogbo oro tole mu
inu eda ma dun.
Won ni opolopo nkan lara ti awon eda miran koni, ti egbo ba wa ni ara won tabi ti won ba se are, ara
won a tete ma ya, won a si tete ma wosan kuro ninu aisan to ba wa ni ago ara won.
Won ni ebun fifi enu so opolopo nkan ti won ba fe, won tun ni afani lati ma ko sile, won le fi oro enu
won jeun bee si ni won le ma fi iwe kiko na jeun.
Idi niyi ti won fi fi enu ko wipe awon omo yi le se ere ori-itage, ati wipe won tun le je olutaja.
Ikilo:
Awon omo yi gbodo sora nibi a nse nfafa pelu eiyan, tabi a nbayan du nkan.
Kokoro meji yi losi ilekun orire won:
Ifokantan ati ikapa-emi-ara eni.
Ki won gbaju mo ise ojo won.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KETALA OSU (13th of the month, 1+3=4).
Awon omo tia bi ni ojo yi feran nkan ibile, molebi won ati adupo ti won ba wa.
Nipa kia nife si nkan, ojulowo (original) nkan ti awon omo yi ma nife si.
Won je eda kan ti ki nku giri se nkan tabi ki won ma kanju se nkan, rara! won yoo koko ronu nipa re
dada, ti won a si wo oye si, atiwipe won a tun ma gbe ero le igbese kankan ki won to dawo le ise na.
Awon omo towa labe onka yi na feran ki won ma sise akikanju ati ise agbara, koda ti won ba nsise
won ko ki ntete simi nidi ise na, bi ise bi ise lo ma se won. Amo won gbodo sora nibi abala yi
gidigidi ki won ma ba sise para won titi yoo wa fi jepe won koni fi aye fun nkan ayafi ise ise.
Awon ti won ma nba awon omo abe onka yi sise, won ma gbara le won tori won ma woye si ise ti
awon omo yi ma nse ati bi won se ma kapa emi ara won.
Nigbamiran awon omo yi ma nro lokan won wipe ise ti awon nse, pe koki nse ona won, ti ironu yi
yoo wa mu won ma bosi ori ise kan si omiran,(tia ba ri iru awon omo yi won ki nsaba ni ise eyokan
lowo), toun ti bi ise ba tun se po lowo won to, won yoo si tun ma ro wipe awon koiti ba ise to romo
kadara won pade. Ki won wa kiyesi ooo, ise toba je eyi ti won mo ju ni ki won duro le lori ki won si
fi awon iyokun sile, Atiwipe eyi ti won ba wa dimu yen na, won gbodo fi igbagbo gbe wipe ona
awon ni yi, amo ti won koba seyi, won yoo ma tinu ise bo si inu ise kan ni, koda iru iwa yi yoo tun
ma ran de bi fife iyawo won tabi fife oko, ti won yoo ma koru lati ile oko kan bosi omiran tabi ki
won koro lodo iyawo kan bosi omiran.
Ona abayo: E gbinyaju kie toju bo inu irawo awon omo yi, kie si wa ona abayo si iwa buruku yi.
Eyi totun wa je iyalenu ni wipe, won je eda toni okan lile, ti won si soro lati fun imoran tori won ki
nfe tete gba imoran eniyan.
Ti won kosi ba sora nibi iwa okanlile yi ati ai mama tele imoran awon eniyan, o le fa ipinlemi fun
won ti won yoo si ma fi opolopo igba wa ni ipo ironu. Iwa yi le ma ba won lo titi lailai ti won koba

51
sora.
Akiyesi:
Awon nkan wonyi ni yoo le tete je ki won ri aseyori si oro aiye won:
Ase pipa won, ati wipe ki won lo ko bi won yoo se ma kaapa emi won, gbigba imoran mo imoran
won

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KERINLA OSU (14th of the month, 14=1+4=5
(iwa awon omo yi yoo fara pe iwa awon omo tia bini ojo karun)
Awon omo tia bi ni abe onka yi nifesi kia ma kuro lati inu iwa kan bosi omiran, ati lati ma rin irin ajo.
Awon omo yi ni ifarada lori oun toba nsele si won, idi ni to fi je pe ipo kipo ti won ba bara won kii
saba je isoro tabi wahala fun won. Won ni ebun oro siso ti yoo sese fun won lati je olukowe tabi
olootu (editor). Won feran ki won ma wa ninu egbe kan tabi omiran, niyi ti won si jo ma sise po dada,
iyen tiko ba si atako tabi ifaseyin nidi ise na.
Ara awon omo yi ki n bale, latari ima kuro lati ibikan bosi ibikan niyi ti yoo si ma sele ninu ise won
ati ninu oro ife.
Won gbodo kiyesi iru iyipada ti yoo ma de ba won, won si gbodo kiyesi dada ki won to ma kuro lati
ibikan bosi ibomiran. Emi aamoju ati ori kunkun nba lara awon omo yi na, sibe sibe won a ma ba ore
pade, won si tun je eda kan to feran tete na ni tita.
Eyi nbe lara oun kan ti won gbodo gbaju mo: ounn nani wipe won gbodo koju mo ise owo won dada
ki won si mama kuro lati inu ise bosi omiran. Won ni awon ebun-abinibi pupo, eyi lo ma nfun won ni
afani lati le se iru ise toba wu won tabi lati dawole nkan ti won ba fe, gbogbo nkan ni awon omo yi le
se, ayafi nkan die tabi oun ti koba wun won lati se.
Alakikanju eda ni won, ti won bati pinnu lati se nkan, ko si nkan tole yi pada kuro ni okan won.
Kokoro (key) to silekun ore won ni iwontunwonsi (balance). Won si gbodo sora si awon ikuro
nibikan bosi ibikan ti won ma n se latari ima ma fe tele ilana kan ki won to bosi omiran.
Amoran:
Lotito awon omo yi mo bia ti se nyanju oro, amo oun toba wonje nani, aima duro sidi ise kan nani.
Amo ki won gbinyaju lati je wipe oun ti won ba bere (start) won gbodo ma yanju re ki won to bosi
idi eto miran. Tori igbamiran won ki nfe ka oro ara won kun ati oro awon elomiran.
E lo ka imoran ti nbe labe onka arun kie sifi se idajo awon omo yi.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KARUNDINLOGUN NINU OSU (15th of the
month, 1+5=6, iwa onka efa yoo yo lara awon omo yi na).
Awon omo yi ni awon ogbon inu ti won fe se nkan tabi fi tun nkan se, won si ni ebun topo si awon
ede miran, ti won ni anfani atilo ko ede kan ti won yoo si ma so. Kosi iru ise ti won le se, sibesibe
won yoo nife si ise ona (art) ni sise, amo eyi tose fi oju ri won a ma se bia n kun ile, tabi awon ti won
ma nko nkan si ara ile tabi sinu iwe lati fi se aworan ati awon agbegilere.
Ima ni ipinu si ibasepo larin molebi ati ore je oun to se pataki si awon omo to wa ni abe onkan yi.
Won gbodo ma fi tokan tokan ba awon oluba gbe won lo, ati nidi ise won.
Kia ma tako eniyan tabi tako nkan je aleebu awon omo yi, fun idi eyi won gbodo ko iwa yi sile, ki
won si ma nife omolakeji won gege bi ara won.
Awon omo yi je oninure ti won si ma ntete ni agboye nkan. Gege bi obi won a ma fi aye sile pupo fun
awon omo won lati le toju won, won si tun ma mo iwonba ara won larin mole bi won.
Awon omo yi ki saaba tete gbo loju, omo ogoji odun won yoo ma dabi omo ogun odun ni tabi kere

52
jube lo.
Awon omo yi setan lati gbe eru eleru tabi ki won ma fe dasi gbogbo eto aiye, niyiti won ko ni se
aroye lorire. Gege bia tise so loke nipa ibagbepo won larin molebi won, molebi won ati ile won je
oun tia won yoo ma gbe sokan julo, niyi ti won le se oun koun lati le fi te molebi won lorun. Ti awon
omo yi ba se ore fun eniyan, won ma reti iru esan ore yen lati owo eni ti won se fun.
Imo (knowledge) ati ati eto-eko (education) je oun pataki ti won tun nife si julo, won si tun ma nifesi
ima se ododo, ati ifomoniyan se.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KERINDINLOGUN NINU OSU (16th of the
month, 1+6=7).
Awon omo tia bini ojo yi, ma saaba rin pupo lati je ojogbon ati lati wa awon asiri kan to pamo sinu
aiye. Won si tun je edakan ti won ma ni anfani lati ma ri oun ti oju lasan kole ri. Igbamiran won a ma
wo ara won bie ni wipe won dayato gedengbe si awon eniyan tokun towa lori ile tabi ki won ma wo
ara won bie nipe ile miran ni won ti wa. Won a ma gbinyaju lati se ofin toto nkan, nigbati won ba ri
nkan ti won nwa tan, won yoo wa ma fi se awon omo araye lore. Won feran ki won ma rin jina ninu
ohun ti won ba gbe dani.
Amoran: Ki awon omo yi gbinju dada lati to pinpin imo toba wa ni owo won dada, ki won si ri wipe
won mo imo nani amodaju,tori imo na yoo ma wulo fun won ni ayekaye ti won ba wa. Koda won
yoo ma ri owo latari re.
Amo oun ti yoo je isoro ti awon omo yi yoo ma koju yoo ma wa latara, ima ro wipe awon yato si
awon eniyan tokun ati ki won ma pataki ara won ju, ti eyi sile fa ki won ko ma ni anu omo eniyan
loju.
Ti won koba sora fun iwa na, o le fa ki awon eniyan ma ri won sa niyi ti o si le fa ikoro nla sinu aiye
won.
Gege bia ti se so pe, awon omo yi yoo ma wa imo, ti won ba wa dada, won yoo ma riran. Ki won
gbinyanju lati gbagbo ninu ogbon ori won, tori oun ni yoo ma je itona fun aiye won.
Awon omo yi ni lati woye si ona ti won yoo ma lo imo ati ogbon ori won si, larin awon ona yi;
Onimo-ijinle (science)
Ojogbon (philosophy)
Olumo-oroinuokan (psychology)
Oluko (teacher).
Amo ki won gbinyanju lati gbo ye dada oo.
Ki won si gbinyaju lati jeki awon eniya ma beere Ibere lowo won.
Opolopo won yi yoo tu ma feran ki won ma ki won ma da se ise won lai pe ekeni si, koda won a ma
gbadun re ju ki won ma sise pelu opo eniyan lo.
E lo ka ti awon omo to oun lo onka keje kie fi kun, tori 16 yoo fun wa ni 7,1+6=7.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OJO KETADINLOGUN NINU OSU (17th of the
month, 1+7=8).
Awon omo tia bini ojo yi je awon ti won laapon ti won si ma n karamasiki nkan, ti Olohun si ma
nbunkun won ni nidi ise won ati ninu owo. Won ki gbarale enikeni.
Won a ma yege nipa idajo, idajo won kede re otito ni. Olusakoso rere ni won ti won si mo bia ti nko
awon eniyan jo ti won yoo si ma dari si ona ire. E ma ri iru iwa yi labe awon omo ti won bini ojo kejo
osu, tori 17 je onka ti yoo fun wa ni 8 (1+7=8).

53
Won ni ebun lati fi oju sun nkan ti won yoo si mo ibi ti oro na ma yoju si.
Ipenija kan to wa fun won ni wipe, ki won sora nipa ife afeju nipa idajo tia ara won, ati nipa aife ma
wo amoran awon elomiran nipa idajo won. Won a ma bara won nipo apase ati oluta-ore.
Awon omo yi gbara won gbo, won ko ki nse iye meji lori oro won.
Ireti awon eniyan lodo awon omo nipa oun ti won yoo se ma nje iwuri fun won, amo ti awon eniyan
bati nse iye meji lori oun ti awon omo yi le se, eyi le fa ki won jawo kuro ninu oun ti won ngba lero
lati se fun won. Awon omo nife si nkan pupo paapa julo lori owo.
Akiyesi:
Awon omo yi gbodo sora fun iwa igbaraga.
Won tun gbodo sora lati ma fi oro won tabi ola won se asehan si awon eniyan.
Won si gbodo je enikan ti yoo ma se itore anu lori gbogbo ere ti won ba ri, paapa julo ki won ma yo
idamewa ere won fun awon alaini.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OJO KEJIDINLOGUN NINU OSU (18Th of the
month)
Awon omo tia bi ni abe onka ojo yi, won yoo ma ni ikapa lati se ilopo meji oun ti awon tia bini ojo
kesan osu le se, tori mesan meji la ma ri ninu ejidinlogun, ati wipe tia ba ro onkan ati ejo papo esan
ni yoo fun wa (9+9= 18 ati 1+8=9). Kosi nkan ti awon omo yi kole se o, ayafi ti ko ba wani ati okan
won nikan lokun. Ebun ti Olohun fun won koni opin rara.
Amo bia ti wa so wipe Olohun yanda lakaye fun awon omo yi to, ni se ni won ma nyo lo diedie, lilo
re ko ki nse fun anfani ara won nikan amo fun gbogbo eniyan ni. Nigba to wipe jeje ni awon omo yi
ma nlo, won ko ki nfa ijogbon, gbogbo nkan won pelu suru ni, amo won ma binu gidi nigbati won ba
pade eni tio je oninu fufu. Amo ni arin yi, won yoo ma ro ni okan won wipe awon ni oye lori ju eni
toun soro lo, won si gbodo sora dada, ki won si ko suru.
Awon na nbe ninu eda ti Olohun ko ipo olori mo, ti won si kun oju osuwon lati ma je alakoso ile ise
kan, nitori emi ima konijo, ati fifun eniyan ni imoran nbe lara won.
Ninu ebun ti Olohun yan da fun, won a ma dangajia ni awon aye bi: ipo oloselu, ninu esin, ise ona ati
amofin. Won si ma ni agboye si awon eniyan. Ninu isemi awon omo yi, won yoo ma lo irin-ajo dada,
lati ibikan si ibikan tabi lati ilu kan si ilu miran.
Won tun ma saaba ni nkan rere lokan lati se fun eda omo araye. Ti won si ma nfe si iyipada rere tabi
ki iyipada rere ma ba awon eniyan, yala adugbo ti won wa, ilu ti won ngbe, ipinle ti won wa, orilede
ti won wa. Idi re re ti awon omo yi yoo ma fi je oludari rere, tori gbogbo oun ti yoo mu irorun wa ni
won yoo ma se.
Amo oo osese ki awon omo yi, ma ri ere nkan yi gba pada sibi ti won ba se si.
Akiyesi:
1. Awon omo yi gbodo je eni ti yoo ma koni mora, ti yoo ma si ma dariji awon ti won ba se won.
2. Gbogbo oun ti won ba ri gege bi ki won fi ibi san ore fun won, ki won gbinyanju lati fi oju fooda.
Tori ti won ba ni lokan lati gbesan awon oun ika ti awon eniyan ba se fun won , oseese ki oro na yi le
won lori
3. Won si gbodo je eni ti yoo jina ninu emi dada.
4. Ti won ba nse ore fun eniyan, opolopo nkan ni yoo ma fi je ibunkun fun won.

54
ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OJO KANKANDINLOGUN NINU OSU (19th of the
month, 1+9=10, 1+0=1).
Awon omo tia bi ni ojo yi, je awon omo kan ti won ni ipinu lati se nkan, ati wipe won ma nifesi ki
awon na dawa lai si ni abe ipase enikeni.
Won ma n sa gbogbo ipa won lati le jeki won de ipo ti won nwa, kowa si bi won sele koju isoro lona,
won ma ngba gege bie ni wipe nkan ti yoo mu awon di eni ominira.
Awon omo yi won gbodo je eni ti yoo ma woye si oro ara re ati si oro awon elomiran. Won si tun
gbodo je eni ti yoo ma gba imoran awon elomiran mo ti won, oro yi le je oun ti won ko feran.
Nigbamiran okanlile a ma ba won ja, eyi le mu won lati maa beru enikeni.
Awon omo yi won a ma dara won loju,papa julo won a si tun ma feran ki awon eniyan ma gbe oriyin
fun won. Won je enikan to ma nsise re dada. Awon eiyan ma nsaba wo ise won to si ma nwu awon
eniyan lori.
Awon omo yi ma nfi emi ara won wewu lati le debi ti won fe de laye won. Won a si ma gbero lati ma
kuro layika ti won ba wa bosi omiran, niyi ti yoo ma jasi idunu fun won.
Won a ma tun saaba fi ife han ati ima se iranlowo fun awon eniyan. Opolopo ero ni nbe lori awon
omo yi, amo ni igbakugba ti awon omo yi ba lo si ona ti koye, eyi yoo ma mu ikoro ati ijakule wa fun
won. Igboya awon omo yi le mu won ma rin kiri ati lati ma bosi ibikan si omiran. Won eni ikapa lati
le yori ero awon eniyan si ona to da ti enikeni kosi ni le se bi awon tise se yi.
Won a ma ronu ni opolopo igba ti won kosi ni se iye meji lati so fun eniyan boya latari ki won fi han
ninu iwuwasi won tabi ki won so fun eniyan lenu ara won.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OGUNJO OJO NINU OSU (20th of the month,
2+0=2)
Awon omo ni won je eda toni anu eniyan loju julo, ti won si ma ntete gbo oro eda ye ati isesi eda; idi
re re ti awon eniyan yoo ma too awon omo yi lo lati gba imoran tabi lati ba won to isoro won, ti won
yoo si tun ma bere fun iranlowo won, niyi to si je wipe won yoo rigba gege bi ibere won. Ko ki nsi
ikorira fun awon omo yi, lati odo enikeni ayafi iyi toba fi iwa buruku kun ise owo re lo kun.
Awon omo yi won ki nburu rara, won ma nife eiyan, oniwapele ni wo, won ki nse ahun. Emi
ifowosopo nbe lara won, won a si ma fi han latori molebi won, de odo ore won ati larin ilu fun eyi
toba nse oselu larin won.
Gbogbo nkan toba rewa, asepo,ati ife lo ma nwun awon omo yi.
Ninu gbogbo asiko ti won ba nlo laye, odo ore won ati molebi won ni won ma nsaba losi ju.
Gege bia tise so wipe won nife si ki won wa pelu awon eniyan ti won si tun nife si ifowosowopo, idi
re ti won fi korira lati ma wa ni awon nikan gege bi Awon Omo Gemini.
Awon omo yi mo bia ti nse ko oro tutu si eniyan lokan lati file tele oun ti won ba nfe.
Akiyesi:
Ti nkankan ba nse awon omo yi ki won gbinyaju lati so jade fun eiyan, amo nipa ise owo won, won
kogbodo ma so gbogbo re fun eniyan, tori eni ti an fe ni won mo, won ko mo eni tio nife won.
Amo sa ebun ara won ni wipe ki eniyan to soro, won yoo ti mo ero okan onitoun.
Ki won si ni igboya gidi lori ise na.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OJO KANKANLELOGUN (21st of the month)
Awon omo tia bi ni ojo yi, ma ni iwuwasi awon omo tia bini ojo keta osu, tori eji ati oka yoo fun wa
ni meta (21=2+1=3).

55
Eya ara awon omo yi ati okan won je oun to ma nsise fun won ni opolopo, to si ma nyi gege bi aye ti
nyi.
Awon na nbe lara awon eda ti Olohun jogun imo lati ma ko iwe, latara ima ko nkan sile. Won si tun
le je onisowo. Won si gbodo wa ona ti idagbasoke yoo ma fi ba ise won. Tori ki ebun to wa lara won
ko ma ba sofo danu.
Akiyesi:
Nigbamiran won a ma wu awon iwa kan, bi ainifarabale lori nkan, papajulo ti won ba nreti nkan won
yoo ma gbe arawon ni emi gbigbona latara aini-ifarabale. Ki won si kiyesi dada tori iwa yi le fe ma
fa akoba fun opolo won.
Ki won si tun rin jina si ibinu ojiji, kodara fun ago ara won rara paapa julo fun opolo won.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJOKEJILELOGUN NINU OSU (22nd of the
Month, Master Number ni Number yi na kose din ku bee sini kose yo kuro).
Awon omo yi ma n ni igbagbo lori gbogbo oun ti won ba nse, ti won si ki nfe ki enikeni ko irewesi
okan bawon tabi ki won ma ni ero meji lori nkan na.
Onka yi je onka kan ti ki ni aniju nkan, iwontunwonsi ni won ma nse afihan re, niyi ti yoo ma lapa
lara oro ati owo (wealth) awon omo na, niyi ti won ko ni ma ni aniju owo, amo iwontunwonsi ni ola
won yoo je. Amo, ki won ma jeki oro yi ko irewesi okan bawon, debi wipe yoo ma fe ma jeki won
ma ni ifeseyin lori imo won.
Awon omo yi ni nkankan lara ti won ki nki kiyesi re, tabi kani asiri to pamo siwon lara; asiri nani
wipe, won ni ore ofe lati ma je olori tabi eni ti yoo ma ko awon eniyan jo, tabi eni ti yoo wa nipo
awon ti won nse adari lori eko kiko.
Ipenija eyokan ti won yoo ni lati bori re oun ni wipe, won gbodo ma ni igboya lori oun ise ti won ba
dawole lati ma se, ti won ba fe bere ise na, diedie ni ki won ma koko bere titi won yoo fi je ki ona na
fe dada.
Oni suru ni awon omo yi. Won ma bani tan/yanju isoro pelu imo ijinle ati lona iyanu.
Nigbamiran ara won ki nbale tosi jepe o le fa ki won ma ni iye meji si oro ara won, tosi jepe won si
tun ma gbe iwa na pamo ti won koni fe jeki eniyan mo.
Ona ti awon omo yi ma nfi gba woye si oro eniyan yato si ti awa eda to kun. Imo ori won kede re
ojina denu, amo ki won gbodo ma gbe emi won lori ise akoko won ti won fe se.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KETALELOGUN NINU OSU (23th of the
Month).
Awon omo tia bini ojo yi ma ni ifarada lori oun ti ba de bawon, eyi ni yoo si ma jeki iyipada lati ibi
kan bosi ibi kan rorun fun won. Ibagbepo won pelu awon eniyan je oun ti ki ni isoro rara, ti so je pe
gbogbo eni ti won ba nba pade ninu isemi aiye won, irorun ni won a ma fi ba won lo.
Okan awon omo yi nsise pupo basi ni ara (body) won na je eyi ti ngbo agboye, idi re re ti si tun le fi
ese won le ona lori tita ogun tabi ima se ayewo nipa ilera ara. 2+3=5, e lo ka onka karun kun oro yi.
Won yoo ma ri ere nla ninu awon nkan wonyi ti won bale se tori won ni ebun lorire, bi oro siso, ere
oritage, olukaroyin, oja tita ati olukoni.
Amo ki won gbinyaju lati lo awon nkan won yi si ona to da.
Won o si gbodo tiju lati ma so oun taba dun won lokan.

56
ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KERINLELOGUN NINU OSU (24th of the
month)
Awon omo tia bi ni ojo yi ni imisi iwa meji lara, nitori 2 duro fun, ima fowosowopo, ti won yoo si
tun ma ran eniyan lowo, ti 4 si duro fun awon alakinkanju omo omo, oni ipinnu, won si se fi okan tan
pelu, fun idi eyi awon omo na je akanda kan ti iwa re yoo ni itunmo laye.
Tia ba si tun wa ro 2 pomo 4, yoo ma fun wa ni efa (6), niyi ti onkan yi ma sise fun iferan awon
molebi eni, won a ma gbe oro molebi won si okan ju won nkan miran lo gege bi awon omo 6.
Won je omo ti ki n se imele rara, tosi ni okun ninu dada, olufokan tan ati oluranlowo ni won saaba
ma nje, amo iwa oju anu nini won le fe fa isoro sinu oro ife won. Fun idi eyi ki won ma iwonba ara
won, pelupelu re won gbodo ma se akiyesi lati mama je ki awon eniyan ma fi owo yepere mu won.
Ki won wo 2,4 ati 6. Alaye onka meta yi lapara won dada.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJOKARUNDINLOGBON NINU OSU (25th of the
month 2+5=7).
Suru nini ati irori je nkan to nse akoso iwa awon omo yi, beesi ni igbesi aiye won yoo je eyi ti won
ma nfi akiyesi si, ki won to dawole oun koun. Won a ma wo iwa yi bie ni wipe awon ko jara mo oun
ti won n se, rara, oun to se koko fun won ni lati ma se suru lori gbogbo ero okan won.
Awon nkan ti won si tun gbodo se akiyesi re ninu isemi won ni: ifokantan, otito siso, atiwipe ori
ododo ni won gbodo gbe ero ibatan (relationship) won si. Lotito o seese ki awon eniyan mama gbo
awon omo yi ye, amo won ko gbodo ro ero ti awon eniyan yi ni won, ki won wa fi ma se iyemeji lori
oro won, rara oo.
Awon omo yi ni ikapa lati ma se iwadi oun to ba ru won loju, koda won a ma wo ni awofini dada.
Iwa yi si je oun kan to ti ko kin jeki won fi owo yepere mu nkan. Won si ni iminsi awon nkankan to
wa lara awon tia bi ni ojo kerindinlogun ninu osu, lotito isoro ojo ti won wa ye ko jo mo ti
erindinlogun yi, amo won fi ye wa wipe, iminsi die nbe lara onka yi.
Akiyesi: awon omo yi gbodo ma lo okan won lati fi yanana oro, bee sini won ko gbodo ko oro si oun
ti okan won ba so.
Amo ki won tun wa sora lori ogbon ori won oo, won gbodo ni ikapa lori re, tori won ko gbodo jeki o
tako ife ti won yoo ma nisi awon eniyan.
Bia ti se so tele wipe awon omo yi ma nro arojinle, amo won je eda ti ki nfi gbogbo igba so edun
okan won fun eniyan.
Amoran:
Iba dara fun iwo omo towa ni abe onka yi lati ma fi ero okan re han si eniyan. Kio si tun gbinyanju
lati ma fi okan tan awon eniyan.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KERINDINLOGBON NINU OSU (26Th of the
month).
Awon omo tia bi ni ojo yi je, awon omo ti won ni imisin okan meta lara, akoko re, 2, ekeji re 6 iketa
re 8.
Gege bia tise mo wipe tia ba mu onka meji yi papo oun ni yoo fi fun wa ni 8. (2+6=8).
Efa (6), ninu onka yi lo nse atokun oluko ti yoo si jeki awon omo yi yege nipa kia ma ko awon
eniyan ni eko, ti won si nife molebi won dokan. Eji (2) yi lo duro fun ima fi emi eni sibi nkan
(concentration/ifokansi). Oun na sini oun se apase imo inu ti eda ma nlo lori ise. Ti onka meji bawa
papo, won yoo bi Agbara ejo (8) sinu isemi eda, niyi yoo fa okiki nla ati ori re nla sinu igbesi aiye

57
awon omo na.
Ejo (8) ni yoo wa bi opolopo nkan si awon omo na lara. E lo ka oro lori awon omo tia bini ojo kejo
ojo, kie si fi se alaye fun aleejo yin, papa julo awon ofin ibe.
Bia tise so ninu onka kejo, wipe ti awon omo yi ba lowo dada tan, wipe won yoo ma fi han latari ima
ra awon oun meremere, won a sama fi han saraye wipe lotito owo na ti de owo awon, koda ti owo na
koba po, won yoo se asehan re saraye, sugbon oju ti awon elomiran yoo ma fi ri awon omo yi ni
wipe, won se ako, rara oo kori be, tori won ki nle pa ore Olohun mo ara ni ooo.
Iwonba suru die lowa lara awon omo yi.
Won si gbodo sora lati le ma jeki awon eniyan ko irewesi okan bawon, tori awon omo araye yoo fe
dan won wo , debi wipe won yoo fe ki won subu, sugbon ti won ba ni igbagbo, ti won si ni igboya ati
wipe ki won se ara won jina dada ninu emi, lati le fi bori awon ota won.
Awon omo yi le je nawonawo, tia mo si baba alaanu, koda ti Olohun ba fun won dada, won a ma je
odidi opo (pillar) kan ni ayekaye ti won ba wa, papa julo ipo olori.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KETADINLOGBON NINU OJO (27th of the
Month, 2+7=9).
Awon omo tia bi ni abe onka yi, feran ki won ma nrin ni ona asiri amo o le pe ki iru ero yi to wa si
okan won, amo gele ti won ba ri imo na tan won yoo se ni anfani fun omo araye lati mafi ko awon ti
ko ni imo nipa re rara.
Gbogbo oun toba ti jomo irin-ajo lilo, ni ma nsaba wun awon omo yi, dandan won yoo se irin ajo,
ninu imo astrology, ninu gbogbo yara ti nbe yara keje na duro fun irin-ajo lilo bee nani 2, 9 ati bebe
lo. Sugbon won ko gbodo se iyemeji lati wonu owo kan tabi ise kan, tori awon owo kan nbe toje
wipe akoko ti eniyan ba reti re, won ki nwa nigbana, eyi ni yoo fi mumi sofun awon omo yi wipe,
igbakugba ti won ba ti ri anfani lati se ise kan tabi lati won inu owo kan, ki won tete wo, ki won si
kuro ninu iyemeji boya yoo da tabi koni da, ati wipe osese ki won ma ri awon eniyan kan ti won yoo
ma soro ti kodara nipa ise na tabi ki won ko lati se ma ise na, paapa julo ise toba je wipe o ma ngba
ojo pupo lowo eni kato yorire (Long term project).
Eka die ninu onka esan kie mu mo oro yi, yoo bara mu.
Ki won gbinyanju ipo olori na. Won si gbodo se ara won na jina ninu emi na.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJOKEJIDINLOGBON NINU OSU (28th of the
month, 2+8=10=1+0=1).
Awon omo tia bi ni onka ojo yi, hmm, lai ni paro kan kan, gbogbo ibi ti won ba de ni aiye yi patapata,
Olori ni won yo ma je nibe, koda ninu awujo ti won ba wa, ki won ma mikan, ipo Olori yoo to si won.
Idi ni wipe, awon omo yi mo bia ti se yanju oro ti kosi ni si ariwo, to si daju wipe won yoo ko awon
eniyan won de ile-ileri.
Amo oo, ki awon omo yi sora lori ore nini won, ki won si gbinyanju lati ma padanu won, tori awon
ore ni yoo saaba ma je igi leyin ogba fun won.
Lotito awon omo yi ni igboya amo, won tun nilo eniyan ti yoo tun ma wu won lori tabi kin won leyin
lori igboya na.
Gege bi ipo Olori tia so wipe o to si awon omo yi, iwa yi yoo ma fa debi wipe, gbogbo nkan ti won
ba nse won koni fe ma wa ni ipo eyin ayafi ipo iwaju. Tiaba woye onkan yi, ao ri 2 nibe, 8 nibe, ti
awon onka yi si ni iminsi won, tia ba si ro 2+8 papo yoo fun wa ni 10, tia ba tun ro 1+0 yoo fun wa
1 ni yi ti ntunmo si Olori.

58
Lotito iwa agidi inu nbe lara awon omo yi tosi je wipe won ki ntete gba imoran boro paapa julo lori
oun ti won ba ti fi okan si, o ma nle lati yi okan won pada kuro nibe. Beesini iwa imotara-eni nbe ni
ara won ti iwa yi na si ma han ninu ise won, tori re lose ma nle fun awon omo yi lati gbe adehun pelu
elomiran, tori oseese ki won ma mu adehun na se.
Ki won sora fun iwa yi, ki won ba le gbadun ipo Olori ti won ba wa, paapa julo ibinu ojiji ati iwa inu
lile.

ALAYE LORI AWON OMO TI BI NI OJO KANKANDINLOGBON NINU OSU (29th of the
month, 2+9=11).
Awon omo tia bi ni ojo yi, won feran ki won se nkan won nipa ti emi (spiritually), kosi nkan ti won
le fe se laye won, won yoo ma gbe gba ona emi ni, niyi ti won yoo si ma se afihan re ninu isesi won,
Won a ma ri opolopo nkan lati oju orun, ni yi toun tumo si wipe ariran ni won.
Ki awon omo yi lo mo daju wipe kosi gbogbo nkan ti won ba ba pade tabi ti won ba nkoju, inu
kadara won ni gbogbo re ti nwa, won si gbodo gbafun kadara won be.
Ibere isemi aiye awon omo yi ma nfe ni idiwo die tabi ki won ma ri awon isoro kankan ati igba ti
won ba losi omo ogbon odun losi oke.
Ni arin awon odun yi, aiye won ma nsaba sun won, tori idagbasoke ko ki nfi ba waye. Sugbon ti won
ba ti n ri awon akiyesi yi, ki won diro mo igbagbo won dada ki okan won ma ba ye.
Won ni oun pupo lati se laye, amo won gbodo mo bi won yoo se dirawon lamure nipa iwa owo won
ati bi won yoo ti se ma se idajo, won gbodo se akiyesi awon oun tia ka kale yi, koto di wipe won yoo
fe ma dawo le ise kan. Gege bia ti se mo wipe ki igi tole wu, yoo ni nilo itakun.
Bakana, meji ni oro won yoo ma fe ri, nigbakan won yoo ri idunu nigbamiran ewe, won yoo ri
idakeji. Won si je eda to ma ntete ni ipalara tabi bo sinu wahala kan, oro si ma ntete su won, ti won
ba wa ni ipo yi, ko ki nsaba si igboya fun won mo, koda yoo ma fe daru mo won lowo, toun ti bi won
se loye to.
Amo sibesibe, won yoo si nife awon eniyan, ti iwa rere yoo si tun lekun ninu iwa won, pelu iwa pele.
Ti oro won ba dayo tan, won yoo ni okiki to ga, ti won a si gbajumo pelu.
Kokoro ti yoo si ilekun anu fun won ni wipe, ki won ma se anu fun awon eniyan, eyi yoo mu ire
wole wa fun won.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BINI OGBON OJO NINU OSU (30th of the month).
3+0=3 nani esi yi, ki won lo ka oro awon toun nlo, onka keta.
Amo ooo, ki won sora lati ma fi akoko won sofo lori, afe-aiye. Tori akoko ko duro de eni kankan.
Won si gbodo ma so ero okan won sita, ati oun ti won ba nro lokan. Paapa julo oun to se pataki julo
ni ife, won si gbodo ma fi han dada latari ifarakora (Romance).
Arin opo eniyan lo dara ki awon omo yi ma gbe. Eyi to je agbara onka yi ni wipe, yoo ma bi oye si
won lara. Ki won si tun gbinyanju lati ma se aseyege ninu ise won.

ALAYE LORI AWON OMO TIA BI NI OJO KANKANLELOGBON NINU OSU (31st of the
month, 3+1=4).
Ikilo ni awon omo yi yoo gba;Ki awon omo ma tele imo ijinle ori ogbon won, ti won ba si ntele o ti
di dandan kio se atona won si bi ire.
Lotito awon omo yi ni otito, bee na sini won se fi okan tan. Awon omo yi ko feran lati ma ko awon
nkan ti ko wulo jo tabi lati ma dari oro lo sibi ti ko ye ko wa. Ebun won yoo ma jeki awon omo yi na

59
le se olori ayakeye ti won ba wa. Ki won sora fun agidi inu.
Ki won lo ka oro to wa labe onka kerin (4), ki wom si fi oye gbe, yoo baramu.

60
IDUPE
Al hamdulilah, Al hamdulilah, Al hamdulilah Robil-alemeen.
Ope ni fun Olohun Oba mi agblagba oye, Aterere kari aiye, Olufini ni iro-idunu lori oun ti awa eda
nse.
Modupe pupo lowo Re, fun anfani nla ribiribi, to fun lati tun te iwe yi jade, emi mo wipe ko ki n se
mimo se mi, bee sini ko ki nse imo ori mi, bi ki ba n se ore ofe re to fun mi lati ma se iwadi lori awon
oun to pamo.
Ope mi tun wa lo si, Odo Planet tia n pe oruko re ni, Jupiter pelu Mercury, ikunlowo awon planet
meji yi je oun ara ti oye eda le gbe lasan, papa julo ati fun onka kankanla tia mo si (11), ti oun na tun
se atana mi de bi ti mo se iwadi de yi.
Modupe lo si odo awon olugbani ni imoran lori iwe yi, ati olute iwe yi, Mr. Akinroye Salam, fun
opolopo ise ti won se, ati awon eyowo ti won se lori iwe na, koto di wipe o gba tite jade. Ki Olohun
si tun bami lekun Albarka Mr. Akinroye na, fun igbani ni iyanju lori bi iwe se gba kiko, tio si gba tite
na.
Mo wa fi kiki mi yi, ki gbogbo ololufemi patapata ti won se alatileyin mi de ibi ti mo bade yi, Ki
Olohun siju anu re wo gbogbo wa, ko si tun fi ike re ke wa.
Mo ro eyin, Olukawe yi wipe, kie fi ara bale ka iwe yi dada, kie ka ni akatunka, eyi tio ba si fe roju
ninu re, kie kan simi lori ero alagbe kami, tabi lori ero aiyelujara, Whatsapp ati Facebook (Akindele
Sodiq, Olumide).
Eyi kowa ni je, asemo, gbogbo igba ti Olohun bati n si lakaye sinu imo kankan tabi omiran, ao ma fi
se imona fun omo araye.
Adehun ni adehun, yoo juwa se amin, iwo omo iya mi, gbinyanju ko se akiyesi ebun ti Olohun fun e
kosi lo si ona to peye, tori kosi eda kan ti Olohun ko fun ni ebun kan si omiran, gbinyanju ko wa,ko
ma ba ku moe lara.
Emi ni ti yin tooto.
Dr. Akindele, aji fi gbogbo igba wa imo kiri.

61
62

You might also like