You are on page 1of 45

OGUN AWENU ATUDE TODAJU

A OLO WA EWE GBURE DIE ATI EPO OBO DIE,


A O GUN PAPO DADA, AO POPAPO MO OSE
DUDU, A O MAFI EPO PUPA PARA WA KA TO
WE OSE YEN. (ODAJU PUPO)

AGBO AWENU ATUDE ASINA TIPATIPA


TODAJU
Ao ge die nibi irun ori wa, ewe ewuro (201),
efo yanrin (201), ewe rinrin (201), ako alangba
kan, abo alangba kan, ere sile ajeobale die,
mafiowokan omo mi tutu die, ota omi kan,
Ao ko irun ori wa tele ape, a o gbe ako alangba
le bi aaye ni o, a o gbe abo alangba le a o ko
awon igba ewe le, a o wa ko awon ewe to ku le
lori a o fi ota yen le lori, a o gbe siwaju ita lori
okuta meta ni ale moju, to ba di deede aago
merin idaji a o gbe le INA, a o se fun bi wakati
kan, a o ti pon omi odo meta sile ninu bucket ti
a fe fi we, a o lo ja ewe iyalo ff kan a o gun mo
ose, a o wa yo omi yi mo omi ti a pon yen ki o
le to wa we, a o te aso ff sile a o we le ori aso
yen, a o wa gbe ape ati a won n ka n to wa
ninu re sinu aso ti a duro le we yen, a o so po a
o lo ri mole sinu Igbo.

OGUN AWENU TODAJU


EWE IYALODE FUNFUN KAN
OROGBO KAN
AKO KAHUN DIE
OSE DUDU DIE
AO LO GBOGBO RE PAPO, FUN IWE EKAN
PERE
AO FI WE NI ALE, NI GBA TI A KO JADE MON
RARA
NB : AO FI EPO PUPA PARA KI A TO WE OSE YI

AWENU : 1
EWE TABA IBILE OOJO
AO GUN PELU EPO OBO
AO FI KO OSE IWE KAN
AO FI WE

AWENU 2 EWE BOMUBOMU


EPO OBO
OSE DUDU
AO GUN PAPO,
AO LO FI WE NI ODO TI NSAN,
AWENU : 3 EWE IYALODE 1 OROGBO 1 AKO
KAHUN
AO LO PAPO, PELU IWE EKAN PERE
AO FI WE NI 11PM
AO FI EPO PUPA PARA KI A TO WE ISE YI

ASIRI AWENU/ATUDE
AO WA ERU ALAMON META EWE ALUPAIDA
META
SISERE: AO MU ERU KAN AO SO EWE
ALUPAIDA KAN MON LARA AO GUN AO KO NI
OSE IWE EKAN AO KO SORI KAINKAIN
TUNTUN KAN BI AO TI SE METETA NI YEN AO
WA LOSI ODO TONSAN AO FI EPO PUPA PARA
AO MU KAINKAIN KAN AO KOJU SIBI TI ODO
TINSAN BO AO KO EYIN SI IBI TODO NASANLO
AO BEERE SI NIWE TABA WETAN AO JU
KAINKAIN LAJU EHIN AO JADE SITA AO TUN
FI EPO PARA AO TUN WE BI TI AKOKO, BENI
AO SE WE ELEKETA...

AWENU TABI AWEBI TODAJU TOTUN MASINA


ewe awede tutu die
orogbo tutu kan ao wa gun mejeji papo mo ose
ekan pere
ao mu lo si odo to san ewe ejinrin ni ao fi se
kanrinka re sugbon ao fi epo pa arawa ki ato
we oseyi odaju

AWENU OWO AYE KURO LARA TODAJU


Ewe iyalode eyokan
Orogbo eyokan
Ako kohun die
Ose dudu die,
(Sisere) ao gun awon eroja yi pomo ose dudu ti
alewe lekan pere, ti oba di ale ni awole sun, ao
fi epo pupa para ki ato we ose yi,

*AGBO AWENU FUN EYIN TI OGUN KINSISE


LARA RE TABI FUN IWO TI OWO BAPO
LARARE*
ELO BAMI WA EWE OOWO TUTU,
AOGBO EWE OOWO YI NINU OMI TOBA TOWA
WE,AOWA SE IDOTI RE KURO,TOBADI ALE
TAFE LOSUN,AOWA FI EPO PUPA PARAWA
LATI ORI DE ESE,AOWA OMIYI WE PELU OSE
RE, TABAWE TAN, AO GBODO JADE SITA MO
OO,
OSE RE,,, AOGUN EWE OPARUN PAPO MO EPO
OBO,
AKIYESI PATAKI,,,TABAWE IWE YI TAN,TOBA
JEPE OWO PO LARAWA,ARA YIO MAYUN WA
GAN,KETI MOPE OWOPO LARA YIN NIYEN,
LEYIN OJO KETA,AO TUN SE IWE YI,LEYIN OJO
KETA,AOTUN SEBE,

OGUN AWENU
EBAMI WA OMUDO/OJELE EWE AKOKO ATI
OJELE EWE IYALODE FUNFUN,AO GUN PAPO
AO WA FIKO OSE,AO TUN JA EWE MEJEJI YII
AO GBO DAADA AO KO AWON EWE YII JADE
AO KO SILE LE,AO WA GUN SI ORI EWE YII AO
WE LE LORI PELU OSE YII.
NOTE:- ALE NI WON MA NWE ISE YII AO SI
GBODO KO EWE YII KURO TITI TI ILE YOO
FIMO.

OGUN AWENU ATUDE TODAJU


A OLO WA EWE GBURE DIE ATI EPO OBO DIE,
A O GUN PAPO DADA, AO POPAPO MO OSE
DUDU, A O MAFI EPO PUPA PARA WA KA TO
WE OSE YEN. (ODAJU PUPO)

OGUN AWENU TODAJU


EWE IYALODE FUNFUN MEJE
OROGBO META
AKO KAHUN DIE TABI KANHUN BILALA
OSE DUDU DIE TOTO YAN WE LE MEJE
AO LO GBOGBO RE PAPO, FUN IWE E MEJE
PERE
AO MA FI WE NI ALE, NI GBA TI A KO JADE
MON RARA
NB : AO FI ADIN EYAN PARA KI A TO WE OSE
YI.
AKIYESI PATAKI.
* KOGBUDO SI IBALOPO LARIN OJO MEJE YI
OO
*ASO FUNFUN LEO MAFI BORA FUN OJO MEJE
YIO. EKOSI GBUDO NU ARA TI EBATI WE TAN.
JEKI OMI NAN GBE MON E LARA

AWENU TI AFI NBOSO OSI DANU LORUN:


ISU OGIRISAKO AO GUN KUNNA NINU ODO
AO PO PAPO MOSE DUDU AO WO ASO TIA TI
LORI DAADAA AO DURO SINU AJADI APERE
LODO TO NSAN AO FI ASO NAA WE PELU ASO
YEN LORUN TI ABA WE TAN AO BO ASO YEN
SINU AJADI APERE YEN AO MAA GBE APERE
YEN BO NILE ASO NAA YIO BA ODO LO.

2:IWE ASINA TI AFI NBA ALAANU PADE


ORI OKA KAN AO YIMO INU ASO EGUNGUN
AO WA DINI IKOBERE OWU DUDU ATI
FUNFUN AO JO PELU ODINDI ATARE KAN AO
WA PO LOSE DUDU AO MAA FIWE LARAARO
3:AWENU TI IDAAMU BA POJU
:EGBO TUDE,OPOLOPO EKOLO AO BU IYOSI
EKOLO YEN LARA AO WA GUN PAPO MO OSE
DUDU TO PO DIE AO JO OMI IGBIN KAN SII AO
SO IGBON YEN NU AO LO FI OSE YEN WE
SODO TO NSAN PELU KANKAN META
1:AO FI ADI PARA KI ATO WE TI AKOKO
2:AOFI EPO PARA KI ATO WE EEKEJI
3:AO FI OYIN PARA KI ATO WE ELEEKETA.
TI ABA KURO LODO AO TA EPO SOJU ONA AO
TE MOLE KI ATO MAA BO NILE.

4:AWENU(ALAKOTAN)
ORI EYELE KAN AO GUN PAPO MO EFO OSUN
AO WA PO MO OSE DUDU
AO MU EYELE KAN LO SODO TI ABA FE WE AO
PE OFORE BAYII:
ALAKOTAN NI NSAWO WON LODE ISALU AYE
ALAKOTAN NI NSAWO WON LODE ISALU
ORUN
OSUN GBEGEGBEGE MOWA FI EJO ORI MI SUN
E,EYELE KI NWAYE TIRE KO SISE,TOTUN
TOSIN LEYELE FI NKORE AJE WOLE AO SE
ADURA SII AO FI AO PA EYELE NAA AO FI
EJERE PA GBOGBO ARA WA AO FI OSE NAA
WE SODO YEN

AWEGUN WEPE DANU TODAJU.


Elo wa egbo tude tutu ati ewe tude, ewe ati
egbo igi iyalode mejeji die die, eepo obo die,
ewe ajeobale die, tobaje pe obirin lafe se ise yii
fun ata ijosi meje, sugbon tobaje wipe okurin
ni ata mesan ni a ma lo.
SISE RE NIYI
Ao ko awon egbo ye sori okuta, ao pa pepepe,
ao yo igi inu re danu, ao gun epo arawon po
mo awon ewe ye pelu ata ijosi ye, ao wafi ose
dudu ti yio towa we fun ojo meta ko.
LILO RE .....Ao lowa ewe ejirin wewe, oun ni
ao fi se kainkain fun, ao ko ose ye sori ewe
ejirin na, ao lowe lodo to nsan, ao we fun ojo
meta lerawon pelu fifi epo pupa pa ara..

ỌṢẸ AWEBI WEPE IPONJU DANU TODAJU


Egbo tude, epo obo ,ako kahun, ao gun po ,ao
po mo ose dudu,ao ko sinu ike funfun kan,ao
ma fiwe nigbakugba.

AWENU TABI AWEBINU TODAJU


Ao lo wa ewe alupaïda 16, eso werenjeje 16,
eyo atare 16, ao lo won po yio kuna daada, ao
pomo ose iwe ekan soso, ao lo si odo to nsan,
ao fi epo pupa para, ao we pelu kainkain
tuntun ibile

OSE ATUDE TO DAJU


Egbo tude, ewe peregun, epo obo, ata ijosi. Ao
gunpo mose dudu, ao pin si ona meta, ao lo we
si odo to nsan, kanhinkehin akoko ao fi epo
pupa para kia to we ose yi, kanhinkehin keji
aofi ori para, kanhinkehin keta ao fi oyin igan
para kia to we

AGBO AWEBI BURUKU DANU NINU AYE ỌMỌ


ẸDA TODAJU
Ao ko Ẹru awonka, eyin adie ibile kan ati ori
Ako etu kan tele ikoko agbo, ao wa ko ewe rere
ati ewe gbegbe le won lori, ao se yio jina
daadaa, to ba di ale, ao gbe lo si ibi ti ao ti we
agbo na. Ao se adura si daadaa lehin ta ba ti pe
ohun yii si tan ào wa fi wẹ sinu koto kan pẹlu
ọṣẹ asina kan ta ba ni lọwọ......
OHUN RẸ _GBEGBE KO GBE IBI KURO LARA MI
LONI 3X, ERUN KO RU IBI ARA MI DANU
LONIO 3X, RERE KO RE BI KURO LORI MI
LONIO 3X, ETU KO TU IBI KURO LARA MI
LONIO 3X, NITORIPE ORI ADIE KI NBURU TITI
KI O YE EYIN DUDU, KI ORI MI MA BURU
LAELAE OO. A KI KA ERU MO OHUN OBE
LOJA, KI WON MA KA EMI LAGBAJA OMO
LAGBAJA MO OHUN BURUKU OO 3X, KI WON
MA KA MI MO IKAKUKA LATI ONI YI LOO, KI
ARA BẸRẸ SI NI DE MI SI OHUN MEREMERE
ORE NLA LATI ONI YII LỌỌ

WIWE AMI BURUKU TIO JE KI ISE JE LARA


KURO NI KIA KIA
ao wa ewe Bomu Bomu meta, pelu egbo tude
oojo die, ao gun papo Mon ose iwe ekan peere,
ao wa gbe koto die si eyinkule wa, ao wa we
ose yen ninu koto na , ao wa bo kehin kehin ti
afi we yen sinu koto yen

IFA ATUDE PEGUNRUN TO MAUN PA GBOGBO


EGUN ATI RAN DIRAN RUN LORI TI WA
.Ao wa omunu ewe peregun meta, ao gun
pomo Ose dudu........ao wafi iyere osun te ifa
ogbe irete, ao wa pe gbolohun re si, ao wapo
mo Ose iwe eekan, ao mulosi odo ao lo we Ose
na, Ale po Ose yi ko po tia bati fewe lao mabu
die die, ao sima pe gbolohun re si Iwo ba tia
bati bu nibe...............OFORE..............AKINMOLA
NI ELEGUN TIO KOKO GEGUN NILE
AYE3*,.......EL
EMO AWO ASAGEDE LO KOKO SA IGEDE NILE
AYE3*,.........AJAGUNMALE TE AWO ATASE LO
KOKO TA ASE NILE AYE3*,...........ARUGBO ILE
ABORI KOKO3*,.........AGBALAGBA O GBE
KEREGBE LO ODO3*,.................Awon maarun ni
won pa wopo pa Omo orisa je si oja ejigbo
mekun, Orisa gbo o faraya o wole omu ada
orisa re.......oun losi ile orunmila,......orunmila
ni kilode
Oni Akinmola to Koko gegun nile aye
Oni Oni Elemo Awo asa igede tio koko sa igede
nile aye
Oni AJAGUNMALE te Awo atase tio koko ta ase
Nile aye
Oni Arugbo ile abori koko
Oni Agbalagba Imule ogbe keregbe lodo
Oni awon mararun ni won pa Omo oun je si
oja ejigbo mekun.......Orunmila gba Ada lowo
orisa, o mule esu odara lowo,.......Esu odara ati
orunmila won nlosi oja ejigbo mekun, Nigbati
won de oja ejigbo mekun,
Won ba Akinmola to Koko gegun nile aye, won
be Lori, won ni Gbogbo egun enu re ti pare,
Won ba Elemo Awo asa igede tio koko sa igede
won be Lori, won ni Gbogbo igede enu re ti
pare,
Won ba AJAGUNMALE te Awo atase won be
Lori, won ni Gbogbo Ase enu re ti pare,
Won ba arugbo ile abori koko, won be Lori,
won ni Gbogbo agogo enu re ti pare,
Won ba agbalagba Imule o gbe keregbe lodo,
won be Lori, won ni Gbogbo, Akadi firaku re ti
pare loni yi............EMI OMO langbaja
epe oso, epe aje, epe lebo loogun, epe
babalawo, epe emere, oti pare lori mi Loni yi
ooooooo.
Obinrin kan wa ba won nibe, oni haaa emi
eyan lepa lopo bayi, Orunmila boju weyin
oniki Eje ma jade nidi obinrin na, Eje si bere
sini jade ni Idi obinrin na tulutulu, obinrin na
sare loba oko re, oko re wole o mu apo, o mu
oko, o mu orun, odi oja ejigbo mekun, Nigbati
oko obinrin na de oja ejigbo mekun, oba
orunmila oni haaa baba Mio mo wipe eyin
lewa nibe, bi eku leungba emi o mo, bi eja leun
gba emi o mo, Orunmila ni obinrin re lokoba
gbogbo obinrin aye, orunmila ni bi eje yio se
maa jade niyi lati ojo kini titidi ojo kaarun,
tobadi ojo kefa ki oko re ki oko bo ni idi
okunrin ni yio fibi.
Orunmila ni esu odara gbe ori Akinmola to
Koko gegun nile aye, won gbe sinu koto kan
won wa yerupe bo, won ni ko tun gbodo gegun
mo Lae Lae
Won gbe ori Emi langbaja Awo asa igede sinu
koto kan, won wa yerupe booo won ni kotun
gbodo sa igede mo Lae Lae,
Won gbe ori AJAGUNMALE te Awo ata se tio
koko ta ase Nile aye sinu koto kan, won wa
yerupe bo, won ni kotun gbodo ta ase mo Lae
Lae
Won gbe ori Arugbo ile abori koko, sinu koto
kan won yerupe bo mole won ni kotun gbodo
si agogo enu re mo Lae Lae
Won gbe ori agbalagba Imule o gbe keregbe
lodo sinu koto kan, won wa yerupe bo mole,
won ni kotun gbodo sa Akadi firaku mo Lae
Lae
Orunmila wafi Ada le esu odara lowo, oni wipe
kio lo sa igi ona wa, esu odara lekini igikigi
lolo sawa, esu odara loni ekeji igikigi lolo
sawa......esu odara loni eketa igikigi lolo
sawa.........Arunmila gba Ada lowo esu odara
Orunmila losa igi ona wa, o wa risi arin awon
mararun,
Orunmila ni igi pa epe run lao mape ni
peregun,........Odo dun ni peregun daso tie, odo
dun ni kiun Mari batise, kiun Rona gbegba, ki
ire aye mi kio tomi lowo ni kia kia, ao Se adua
si lopo lopo.......ao wabu iwe ekan ninu ose
yan, pomo iyere osun tia pe gbolohun si yan,
ao lofi we ni odo toun san

AGBO ITUWO AYE


ao wa ewe botuje (ewe lapalapa) fun fun ti yio
po daada, ati pupa re, ao wa fi epo obo tele inu
koko agbo yen, ao wa ko ewe botuje pupa yen
le Lori, ao wa fi eyin adie ibile kan si , ao sese
wa ko botuje fun fun yen le Lori, ao wa bu omi
si daada, ao wa se lagbo , ti oba ti tutu Dada ao
wa ko gbogbo awon ewe yen sinu ilele ile iwe
yen , ao duro si ori ewe yen, ao wa bo epo eyin
yen , ao se ADUHA si DAADA, ao wa ju senu
lekan na jee, ao wa fi omi yen sinra ninu ile
iwe yen,,
Akiyesi,, ti aba we agbo yen tan ,akogbodo jade
mon ooo, Ale ni ama nwe agbo na ooo,

aseje owo todaju,ewe imi esu oojo eyoka ao lo


mo iyere meta ao fi din eyi ororo kan je lepo
niyo ninu koko aseje ao wa ogorun naira
(#100)a o fi kale ao se adua iye ti a ba fe si ao
wa so aseje sori owo naa ao wa je ase je naa a
o lo fi owo na se sara fun onibara pelu adura.

*Aseje Ebe awon agbalagba tiwon fi dari oore


siwa.Paapa julo awa ti andayan loun*
Ewe ajeobale,iyere,a o lo won papo.A o fise
eran ewure ti ao gesi merindinlogun
(16)leponiyo. A o fi iyereosun te Osa meji,a o
pe ofore si, ao je..
Ohun re:---- Aganiwere, Osungbokereniyi, Erin
nii se onipe okinkin, obinrin nii se ibi lotu Ife,
won de ile Orunmila, won o ba Orunmila nile,
Osunnaya aya re ni won ba nile. Won ba
aganiwere nile, won ba osungbokereniyi nile,
won ba erin nii se onipe okinkin nile. Won rin
saa,won de orita meta nidi ope eletu meta, nibi
won ti pa eran eniyan kale, won n je e. Ni
Orunmila ba dele, koba awon omo awo re nile,
osunnaya aya re n loba nile. O ni awon omo
awo oun nko? Osunnaya ni won ti lo
bayii,Orunmila rin saa o de orita meta nidi igi
ope eletu meta,o ba awon Iyami osoronga nibi
won ti pa eran eniyan kale,ti won ti n je
e.Orunmila ni en lee o,won nii ooo.O ni se e
bami ri awon omo awo mi? Won lawon o ri
won.Orunmila yise pada ni nlo,boti rin
saa,okan ninu awon Iyami ni Orunmila nu-
un,gbogbo nnkan ti awon n se nihin loti
ri,arinu rode ni.Won pe Orunmila pada.Won ni
awon omo awo Orunmila lose awon nigbo n ni
awon naa fise won nigbo,ni awon fi pa won
kale ti awon fi n je won.Orunmila ni e bami
gbe won jade,won gbe aganiwere bo o de,won
gbe osungbokereniyi bo o de,won gbe erin nii
se onipe okinkin bo o de.Orunmila bafi ohun
iyere sa aro,o ni aganiwere omo olomo
ree,osungbokereniyi omo olomo ree,erin nii se
onipe okinkin omo olomo ree.Awon iyami ni
kinni Orunmila n kesi? Won ni se orunmila o
mope ti awon ba pa eniyan kale tan,awon a
maa ji.Orunmila ni e bami ji won.Won ji
aganiwere,won ji osungbokereniyi,won ji erin
nii se onipe okinkin.O ni kinni a o se ti awon
omode wonyi o fi ni kumo? Won ni ki
orunmila o toju eran ewure ki o gesi
merindinlogun,ko toju ewe ajeobale pelu iyere
kofi see leponiyo. Nje eye Aje mide eye niforo
moba,eye mobamoba niforo.Eye Aje komo ri
ori omo awo bale.Ewure loniki olowo oloro o
maa bami re towotowo owo won.Osa meji ni e
fi sa gbogbo ibi araa mi kuro,Osa meji loniki
olowo oloro o maa sa wa bami.(Iyalaya adua ki
awon tolaiye maa dari awon ti ori ti segi ola
fun lawujo si odo wa.)

AWURE ASEJE EYONU TANFIRI OWO NA ISEYI


TUNSISE BIBO ....
ASEJE AWURE OWO
EWE OPOTO
EPO JEBO
EDO MALU ONA 16
AOLO EWE YIPO PELU IYERE aose lepo niyo
Tiaba ra Edo MALU ye dele Aogbodo fi obe ge
oo aolowa Efon NI aofige SI 16 Aose jina aoso
sori ossuka AOWA PE Password resi...bayipe
GBOGBO IGI nidarijo wonbasiri OPOTO ,
gbogbo araniwon DARIJO Edo eran , Akisa IGI
jebo komabo pada ATI OKUNRIN/ OBINRIN
/olowo ilu/ Olola ilu kewa DARIJO BASIRI e mi

ASEJE ASIRIBIBO
Ewe aje Sawerepepe Igbin Iyere 16 Iyo Epo
Sisere- ewe aje, sawerepepe,iyere,ao lo papo ti
yio Kuna dada,ao da sinu isasun ti aba lotan,ao
fi Igbin sinure,lepo niyo die,leyin ti ati da
gbogbo elo re papo,ao gbe kana,tobati jina, ao
se adura owo ati bibo asiri sinu re ki ato je.
Note-kogbodo kan ile leyin ti obajina tan.
Awenu ti ama kankan we ki ato je aseje
asiribibo yi.
Ata ijosi mesan fun obinrin meje,epo pupa
die,pelu isebe die,ose dudu.Ao lo ata ijosi yen
kuna,ao fi ata ijosi ti ati loyen,ao fi ko ose pelu
isebe,ati epo pupa,leyin ti ati po oseyen papo
mo eloyen tan,ao da osena si ona meta,ao fiwe
fun ojometa ni alale,
Note-omi toloworo lema fiwe isena.

(Atude Aseje),,,,Egbo tude,egbo ifon,ati ata


ijosin ti koni ye, ewe ogbo mesan fun okunrin,
meje fun obinrin,ao gun gbogbo re papo ao da
sinu isasun tuntun,igbin apinu kan ao bo igbin
yi ao ge si ona merin pere, ao fise ni obe pelu
epo ati iyo ti oba tutu ao se adura atude si ao
koje,,,

BIBO_ASIRI_TODAJU_ONI_RICE
Aiwa afara oyin awo lili meta tiwon bo totitori
ipeure meje odindi atare meta #50 tuntun
aojo gbogbo repo ao mafi je rice tiko ni iyo
ninu akogbodo fi obe si iresi na eniyan kan
soso ni ogbodo je rice na

ASEJE_INAWO_ASIRI_BIBI
Aowa igbin nla kan ao bo igbin naa ao lo ewe
sawere pepe ati igbo die papo ao fi se igbina
na ni odidi ninu isasun tuntun ao so obe naa
sori osuka ao se adura si katoje.....
ofore:igbin kifi enure le igi komagun ao wase
adura si katojee

Aseje Osole owo todaju pupo ise ogundabeje


Ise naa lolo bayi
Odidi igbin ti o bonu nla kan pelu isu
tannagbowo, iru woro pelu alubosa elewe ati
ata ijosin 25 iyepe oja ti o tobi ao bu die nibe
ao wa ge igbin yen si 25 pelu owo eyo 25 tiko
luju rara ao wa gun isu tannagbowo iru
alubosa elewe ati ata ijosin papo ao ni gun
owo eyo mo ooo ao wa fise igbin ti ati ge si 25
ao wa se lepo niyo pelu owo eyo yen ti oba
jinna ao wa so kale si ori osuka ao wa mu
iyere osun ao fi te ifa ogundabaje sori obe yii
OFO LOLO BAYI>
Ogundabaje ole 3* Gbewiri Ole 3* Ogboju Ole
3* Ti ohun mo ibiti onikan fi nkan re si
Agbalagba ole abise siosio, Ogbologbo Ole
abiososo gborogboro jiji laji abi gbigbe logbe
abi wiwa lowa ki ologbe owo wa fun emi
lagbaja omo lagbaja ni kio wa fi ile mi hun
tokunrin tobinrin ki won gbe owo apo
meedogbon wa funmi ki ototo di ojo
meedogbon nitoripe ti omode bamu igbo lowo
apa bi agba bamu igbo, Igbo apa lore paa
tomode tagba tokunrin tobinrin wa funmi ki
won maa ko owo apo meedogbon wa funmi ki
oto di ojo meedogbon ifa mo pe o oooo
orunmila mope o oooo kie maa salai dami
lohun to ase
Dandan ao da iyere osun si ao maa je igbin
kan ao maa pon owo eyo kan laa ao maa sope
owo mi di apo nla kan,apo nla meji titi yio fide
ori 25
Ti aba je obe yii tan ao wa lori ikoko ti afi je
sinu igbo dandan ikoko tuntun ni a gbodo lo

ASEJE OLA TI AFINSE ORIRE


Afomo ori igi obi niwonba, ao lo afomo yi pelu
ata ijosi merindilogun kunu dada, ao fa sinu
ikoko aseje kan, ao fi se igbin lepo niyo, ao
gbodo ge igbin yi o, odidi be lao se , ti aba
setan kogbodo kanle mo o, ao gbele ori nkan,
ao wafi iyerun osun te ifa ejiogbe si atelewo
wa, ao ma pe ohun re si bayi wipe, (ohun re)
afomo olowo, afomo olese , ara igi ni afomo
tinse ola tire, lodidi ni olugbo figbin tore fun
ero ona, odidi owonla niki awon omo araye fi
tore fun mi lati oni yi lo, ao se adura si dada,
ao wada iyerun osun yi sinu aseje na, ao ropo,
ao koje, odaju
ELEYI NI ASEJE OSOLE TI KO NAWA LOWO
RARA, TODAJu
Ao ra ponmo bi oni 200# ao ge ponmo nasi 9,
ewe itiponola 16, ata ijosi 16, iyere 16, aofi oti
gulder die san ponmo yi nu ninu isasun aseje
tuntun, ao se aseje yi lepo niyo, aoje aseje na
ni ihoho omoluabi, ao tun wa mu gulder iyoku
le aseje na. ODAJU
AKIYESI: ki ile ojona to su ao gba owo toto 10k
fun ojo meje lai ba obinrin kankan sun titi ti
ojo meje na mafi pe

ASEJE OWO KIAKIA 5OK LARIN OSE :ao lo ra


ponmo dudu ao wa gesi 16 iyere 16 omo atare
16 ata ijosin 16 Ewe efirin 16 Ewe olaa die ao
lo gbogbo re leyo kookan ao ma dasi inu ikoko
aseje ti a fe lo ao se lepo niyo ao so sori osuka
aose adura owo kiakia si ao ko je ao mu omi
aye lelorii dada

ASEJE EYONU AWON AGBA ATI ASINA OWO


TIPATIPA TODAJU
ojele ewe lapalapa funfun eyo mesan 9, ojele
ewe lapalapa pupa eyo mesan 9, ata ijosi eyo
mesan 9, iyere eyo mesan 9, ao loo won papo
mo ara won, ao fa sinu ikoko aseje tuntun kan,
ao wa fi eyin adie ibile ororo meji 2, eja aro
gbigbe meji 2, seje ni obe aseje, pelu adura
ASEJE OWO
eyin agrik 4 ewe sawerepepe oojo ..ata josin
die.. alubosa funfun kan.. omo onigelegele
funfun.. ao lo gbogbo re papo ao fi din eyin
agric yen je lepo niyo
.. odaju ao ri owo ni arin ojo meje ---------
akogbodo sun mon
obirin fun ojo meje

ASEJE EBE AWON AGBA (OSA MEJI)


Ewe ajeobale, iyere, a o lo won papo. Ao fise
eran ewure ti.
Ao gesi merindinlogun (16) lepo niyo. A o fi
iyereosun te Osa
meji, a o pe ofore si, ao je..
Ofore: Aganiwere, Osungbokereniyi, Erin nii se
onipe okinkin,
obinrin nii se ibi lotu Ife, won de ile Orunmila,
won o ba
Orunmila nile, Osunnaya aya re ni won ba
nile. Won ba
aganiwere nile, won ba osungbokereniyi nile,
won ba erin nii
se onipe okinkin nile. Won rin saa,won de
orita meta nidi opeeletu meta, nibi won ti pa
eran eniyan kale, won n je e. Ni
Orunmila ba dele, koba awon omo awo re nile,
osunnaya aya
re n loba nile. O ni awon omo awo oun nko?
Osunnaya ni won
ti lo bayii,Orunmila rin saa o de orita meta
nidi igi ope eletu
meta,o ba awon Iyami osoronga nibi won ti pa
eran eniyan
kale,ti won ti n je e.Orunmila ni en lee o, won
nii ooo. O ni se
e bami ri awon omo awo mi? Won lawon o ri
won. Orunmila
yise pada ni nlo,boti rin saa,okan ninu awon
Iyami ni
Orunmila nu-un,gbogbo nnkan ti awon n se
nihin loti ri,arinu
rode ni.Won pe Orunmila pada.Won ni awon
omo awo
Orunmila lose awon nigbo n ni awon naa fise
won nigbo,ni
awon fi pa won kale ti awon fi n je
won.Orunmila ni e bami
gbe won jade,won gbe aganiwere bo o de,won
gbe
osungbokereniyi bo o de,won gbe erin nii se
onipe okinkin bo
o de.Orunmila bafi ohun iyere sa aro,o ni
aganiwere omo
olomo ree,osungbokereniyi omo olomo
ree,erin nii se onipe
okinkin omo olomo ree.Awon iyami ni kinni
Orunmila n kesi?
Won ni se orunmila o mope ti awon ba pa
eniyan kale
tan,awon a maa ji.Orunmila ni e bami ji
won.Won ji
aganiwere,won ji sungbokereniyi,won ji erin
nii se onipe
okinkin.O ni kinni a o se ti awon omode wonyi
o fi ni kumo?
Won ni ki orunmila o toju eran ewure ki o gesi
merindinlogun,ko toju ewe ajeobale pelu iyere
kofi see
leponiyo. Nje eye Aje mide eye niforo
moba,eye mobamoba
niforo.Eye Aje komo ri ori omo awo
bale.Ewure loniki olowo
oloro o maa bami re towotowo owo won.

ASEJE GBERE OWO KOMI TO MA FI UN GBA


100,000 LARIN OJO META...TI A BA NI EYONU
AWON AGBA GIDI LARA.
Ao lo wa ewe atewogba mewa,ewe
sawerepepe mewa ,ewe ola mewa ,epo
igila,iyere mewa, ao lo ra okan malu odidi kan
ao gesi mewa....ao wa se ni aseje lepo niyo,ao
se asejeyi ni irole ao wa je ni idaji ojokeji lai ti
ba enikeni so oro,ao ma se adua ti aba ti un
je...odaju

ASEJE EYONU AWON AGBALAGBA TABI ENITI


AYE BA NDA LAAMU TODAJU
Eso ako ibepe
Igbin olusango nla kan
Ikoko aseje tuntun kan
SISE RE:-a o lo eso ako ibepe na ti yoo kunna
dada, a o wa da sinu ikoko aseje tuntun na,
leyin eyi a o fo ikarahun igbin olusango na, a o
wa yo igbin inu re kuro, a o wa fi igbin na sinu
ikoko aseje na, a o wa se lori aaro l'epo n'iyo, ti
o ba jinna tan, a o wa so sori nkan.
JIJE:-a o wa so pe "eso ibepe ki i ku iku eporo,
agba ilu, omode ilu, obinrin ilu, okunrin ilu e
wa forijin mi, e wa yonu si emi lagbaja omo
lagbaja, ki i gbogbo nkan mi ma lo siwaju si,
leyin na a o wa se adura si, a o wa je aseje.
Akiyesi:-leyin ti a ba je aseje na tan, a o fi eyin
ororo meta ati eko meta, a o wa ko sinu ikoko
aseje na, a o wa bu epo pupa si lori, leyin eyi a
o wa bo ara wa si ihoho, a o wa fi se adura fun
eleda wa, a o wa gbe lo si orita meta ni dede
agogo mejila oru, leyin ti a ba gbe etutu na sile,
akogbodo bojuwo eyin titi ti a o fi wo inu ile

ASEJE AWON owo


Ewe orijin tutu die, ewe ajeobale tutu die, ewe
awoyoyo tutu die, ao lowon po pelu ata ijosi
die, ao wage eran elede si iye toba wuwa, sinu
ikoko aseje, ao ko awon ewe ti alo yen si, ao bu
omi si , ao wase pelu epo ati iyo, toba jina tan,
ao so sori nkan, ao jeki otutu dada, ao wama se
adura si, ao wa koje, odaju gan ni o, ao gba
owo

ASEJE OSOLE
ewe owu akese egbo akerejupon ewe abamoda
16 ata ijosi 16 a o lo wo papo a o ge okete kan
16 igbin nla kan a o ge si 16 ao se ni aseje pelu
epo iyo, a o fi iyere osun te ejiogbe sinu re
Ohunre ajikawo 3x ojini kutukutu pile ola 3x
osupa tinu ajere ide la wa aye olasasakalu 3x
ifa o too ge ki o wa pokiki mi lo, abati alagemo
ba da lorisa oke gba, ki awon eyan nla nla wa
mi ri oo ti akese nise lawujo owu ojo ti
akerejupon bata egbo re ni kan lepa ifa oo owo
ti won bolmole ko di temi, ehin ti okete ba fi je
eyin ki fi han egbe re, ti igbin badenudele ni je
ifa ki emi lagbaja je ifa owo a o da iyere osun
na sinu aseje yen a o je
Aseje owo ewe aje sefun sefun eweola die ewe
sawerepepe ata ijosin aolopo moarawonaowa
owo#200 oalomo eyin adie agiric meta aofi
seje bibo asirini odara

ASEJE ATUDE
Egbo tude a lo kunna daadaa,ao da omi osan
wewe(oronbo)ao da sinu ikoko aseje,a o da
egbo tude ti a lo yen si,ao gbe ka ori ina,to ba ti
n ho,ao fo eyin adie agric meta sinu abo kan,ao
po daadaa,ao da si nto wa lori Ina yen,tobati
jinna,ao soka ori osuka,ao se adura si wipe
gbogbo nkan aburu ti awon abinu eni ti fi
pamo si wa lara ki gbogbo e baje ao tun se
adura itude si ao je koto tutu,opari

ASEJE ASETA TODAJU


igbin Mejia,abere oporo odidi kan,ewe
aluki,ewe ela,isasun tuntun, iyere, ata ijosi
koni iiye,epo,iyo,ao bo igbin yen.ao mu abere
yen ao fi gun ni mejo mejo.
OFORE=oso ile ki nfi abere joko×3,emi l-o-l
modi ajiginni arin ginni ×3,aje ile ki nfi abere
joko×3,modi ajiginni arin ginni ×3,bi eranko
bajelo boba jebo ada ewe aluki si×3,modi
ajiginni arin ginni ×3,ewe ela ki Ola emi l-o-l
sowo kio lami somo×3,igbin kin kole e koma
kan×3,emi l-o-l ki nsegun ota mi,Otale-ita
ode,elepeAlasan
ASEJE IMULE AWON AGBA TOGBONA JANJAN
TODAJU BIIKU
Ao wa ewe orijin 16, ewe ajeobale 16, omi
agbon meta, iru woro 16, iyere 16. SISE RE:- Ao
walo gbogbo won papo, ao fise eyele funfun ti
a gesi 16 je lago kan oru ti kogbodo ju belo,
leyina aowa fi aso funfun su osuka, ao su si ita
gbangba, ao wa gbe aseje taseyii lelori, ti yio
mawo sanmo, ti obadi ago meta oru ao fi iyere
osun te ifa osa meji,Ao pe ayajo re si. OFO RE:-
Odi imule nitoripe osa meji niwon fiba eyin aje
mule ni ojo kini, emi Lagbaja omo Lagbaja naa
fi osa meji bayin mule loni, eni orunmila bayin
fi osa meji mule ni ojo kini, eodi lowo, emina fi
osa meji mule lati oni lo oo, ema dimi lowo o,
ki esi ma kobami lati oni lo, ki esi jeki omasese
lati onilo. Ao wa da iyere osun naa sinu obe
naa, lobadi jije. IKILO:- obinrin kogbodo lo
iseyi koma baa wo egbe ooo, toripe ti aba nje
aseje yii lowo awon agba mawa kiwa, won ledi
eranwa tabi ounkoun, kama se beru oo, asile
magbo oun eye won lasan oooo. ODAJU

ASEJE ASIRIBIBO TOUN GBE OWO WA


Egbo tude gbigbe die, ewe ominsinminsin
gbigbe die, ao lo mejeji papo tio kunna dada,
ao wa okan Malu 1, ao ge okan Malu na si 16,
ao se pelu epo,iyo ati ata...ao da ewe ti a lo yen
si ooo..toba jinna ao so sori osuka...ao koje.....
ASEJE OWO KIA KIA
ao wa ewe tanapowo 21, INA re 21, ewe
sawerepepe 21, INA re, 21, ewe aje 21, iru
woro 21, ata ijosin 21, ao lo papo, ao fise eran
malu ti agesi mesan , meje fun obinrin , ao se
laseje , ao so sori osuka aso fun fun , ao se
ADUHA owo kia kia si ,ao ko je,

..ASEJE OWO KIAKIA


.Aolo Ra Eran Maalu Ige Kan Totobi Dada
Agbon Kan Toni Omi Ninu Ewe Sawerepepe
tutu Aolo Ewe Sawerepepe Na Kun na Dada
Aofi Eran Na Sinu Isasun Aoda Ewe ti Alo yen
Le Lori Aowa tu Omi Agbon Yen Si Orire Aowa
se Kojina Ti Omi Agbon Yen Magbe mo Lara
Aoso Si Ori Osuka Aowa Sadura owo Gidi si
Aoje Odaju

Aseje asiri bibo


Eyin adiẹ 6
Ewe abamoda 6
Ewe òdúndún 6
Ata ijosi 6
Eran malu ekiri 6
Edo malu 6
Gulder 2
Ào bọ ẹyin yen ào se gbogbo rè pò lepo niyo ao
sọ sori osuka aṣọ ao je pelu adura owo nla ào
mu gulder méjèjì le lori

ASEJE AWURE OWO


Ewe omisinmisin gogoro, eyin adie ibile merin,
ao lo ewe yi kunna daada, ao fa sinu abo kan,
ao wa jo omi eyin naa sinu isasun ti a fe lo, ao
po ewe ti a lo mo ninu isasun naa, ao fi iyo ati
epo pupa si, ao din gege bi ati n din eyin je, ao
ni je kio jona, ti o ba jinna tan, ao so sori osuka
kan, ao wa fi iyere osun te ifa ejiogbe sinu
opon ifa tabi paper funfun kan, ao pe ofo re si,
ao da sinu obe naa ti a ba pe ofo re tan.
OFO RE : Alapa masise ni oruko ti a npe Ifa
(×3), Amona Owo mare ni oruko ti a npe esu
odara, Oloti kii pe esinsin ko to wa mu oti,
Alagbede kii pe agbe kio to wa pon ada re, oso
to nbe nile yi, e ma pa ohun mi da, Aje to nbe
nile yi, e ma pa ohun mi da, ewe
Olomumuyeye kii pa ohun Oba Orisa da, emi
lagbaja omo lagbaja ti di ewe Olomumuyeye,
omo araiye e ma se pa ohun mi da, kie fi owo
ati ola tun mi se, ao se adura si lopolopo, leyin
re, ao da sinu obe naa, ao je, ao mu ohun ti o
ba wun wa le lori.

ASEJE ASIRI BIBO KIAKIA TODAJU


A o lo oga gbigbe kan tio kunna dada, pelu
#200 tuntun kan, pelu iyere a o lo gbogbo re tio
kunna dada, a o fin din eyin agric meta je lepo
niyo

ASEJE BIBO ASIRI , TI EYAN MA NJE NI OJO


KINI NINU OSU
Ori oka Toni ase lenu eyokan
Oga gbigbe Kan
Eja aro gbigbe Kan
Egun Ori Inaki ile die
Owo eyo tikoluju Kan
Ata josin die
Omi okun die
Agbon eyokan
Ewe atewogbore tutu
Ewe awerepepe tutu
Eyin agric tutu eyokan
Epo pupa
Iyo didi die
#1000/#500
Ao Fi omi okun ati Omi agbon gbo ewe
atewogbore yen, ao wa fun Omi yen sinu ike
Kan, ao wa ju #1000/#500 sinu Omi, ao soak
owo yen sinu omi yen, ao wa suu ewe
atewogbore yen rogodo ao Fi sibikan, ao wa
gun Ori oka yen loto ,ao gun oga yen loto ao lo
owo eyo eyokan pomo Egungun Ori Inaki
igboro die, ao wa da gbogbo re papo, si ojukan,
ao wa lo ata ijosin die po mo ewe sawerepepe
tutu yen, ao wa gbe ape ka Ori aro idana, ao da
epo sinu ikoko aseje, ao da gbogbo nkan ta lo
ati nkan ta gun yen sinu epo pupa towa Lori
ina yen ,ao wa se-se da ewe atewogbore yen
yen lelori, ao wa Fi Omi okun San eja aro
gbigbe yen nu dada, ao Ju sinu re, ao Fi iyo si,
ao wa lo yo owo yen kuro ninu Ike ta soak re si
yen, ao wa lo saa owo yen si abele ile, ao wa da
Omi ta fi soak owo yen sinu aseje yen, ao wa Fi
ideri ikoko aseje yen cover re, to ba ti jinna ao
wa fo eyin agric sinu ike Kan ao Fi sibi po papo
ao da SI Ori aseje to bati jinna mo AO so aseje
yen kaa Ori ok suka, ao ti ilekun mori je aseje
yi Ni ihoho taba ti je tan ao wa wo aso funfun,
ao wa lo na #1000 tabi 500 yen SI ile itaja to ba
tobi akogbodo gba change
AO gba owo titi osu yen ma Fi pari Ni.ODAJU

ASEJE ASIRI BIBO TODAJU


Aowa eyin agric merin,orisi siga meta otooto,
ewe ola die
iyere die, ori, ao fo awon eyin yen sinu abo
kan, ao lo ewe ola yi mo awon eroja yen pelu
siga, aoda paper eyin siga yen nu, aowa po
papo mo eyin yen dada ninu abo yen, ao wa fi
ori yi din je lori Ina, a o so si ori osuka pelu
adura, aowa koje aomu omi aye lelori yio
dawa lamun die, amon aori owo nla gba. Igbati
a ko ba jade mon lo dara lati se ise yi bi ale
patapata, tabi eni ti koba losi ibikankan laaro.

ASEJE ISAN GBESE TODAJU SAKA


Aowa igbin apinu kan
efo gure oojo, ewe sawerepepe oojo,
agbon odidi kan, iyere iyekiye, epo, iyo, ao lo
efo gure pelu ewe sawerepepe ati iyere papo
ao fi iyo ati epo si ao wa fi omi agbon se omi re
toba jinna tan ao so sori osuka ao se adura
owo si lori gbese na wipe onakona ni omi nba
wonu agbon ona kona kie gba ri owo na san ni
kiakia aowa koje odaju dada aomu omi aye
lelori.

ASEJE ASIRI BIBO TODAJU


Efo gure (gbure), oojo, ao lo po mo ata ijosi,
pelu ewe ola die, ao wa lo ra eyin agric mefa,
ao se ao bo epo ara re kuro, ao wa ekiri eran
malu mefa, ao se papo lepo niyo, ao ma je
lokokan, ti a ba mu eyin kan, ao mu eran kan
titi ao fi je gbogbo e tan,
NB: E ma je ki ewe ola yen po ninu aseje yen
ko
ASEJE OWO TODAJU
ORISI SIGER META
EWE OLA
IYERE
ORI
EYIN AGRIC MERIN
IYO DIE
AO YA PAPER ARA SIGER YE, AO YO GBOGBO
EWE INU RE DIE DIE NI OOOOO, AO LO PO
MON EWE OLA DIE, ISE NLA
AO JU ORI SINU KOKO ASEJE, KO YO BI EPO,
AO FO EYIN YE, SINU ABO KAN, AO DA
GBOGBO INKAN TI A LO YE, PAPO MON,
AO RO PAPO DADA,
AO FI IYO DIE SI, AO SE NI ASEJE
AO JE PELU ADUA OWO NLA NLA
IKILO : ISE YI LAGBARA PUPO OO, TI ENIYAN
BA JE, ENIYAN LE BI PADA, YO DAYAN LAMU
GIDI,
SUGBO ENIYAN YO RI OWO BI OLE NI, O DARA
FUN AWON TI WON MAN JE EWE OLA DADA,
IKILO 2: E JE KAN WE AWENU KI A TO JE ISE
YI OOO,
IKILO 3 : E MA SE ISE YI FUN COSTUMER OOO,
ISE YI MA DAYAN LAMU OOO,
EWE OLA DIE NI OO
EWE SIGER DIE NI OOOO
ISE NLA NI ISE YI OO
OJO TI ONIGBO BA MU IGBO, OJO NAN NI
IGBO UNPA , ASIRI NLA, KO SI FUN OMO DE
OOO,
O KERE JU 300,000 YO MU WA

Aseje bibo asiri togbona .


.ao wa ewe ewuro ewe ojusaju ewe awoyoyo
ata ijosin 9 iyere 9 aolo papo mora won aofaa
da sinu ikoko aseje aofi epo ati iyo si ikan orisi
meta ni ama fi se ni nu kaa lo eran malu ki age
si 16 or ki alo eyin agric 6 or ki alo igbin 2 ki
age si 16 ti oba jina aoso ri ori okuta meta ni
awa ni kan ni nu yara aoti ile ku paaa .aobo ra
si ihoho omoluabi ao wa ma se adura owo nla
nla ao wako je

ASEJE BIBO ASIRI TODAJU itana akoko16


ataijosi16 eyin agric merin ori ao lo ina yen ao
fi ori dije ni aseje ao se adura bi asefe

ASEJE ASIRI BIBO


AO LO EWE RINRIN PELU ATAJOSI 16 ERAN
ELEDE TI A GESI MESAN FUN OKUNRIN TABI
MEJE FUN OBINRIN AO SE LEPO NIYO AO SO
SORI OSUKA AO SE ADUA SI AO JE.

Aseje asiri bibo kiakia


Ewe sinkinmini 8
Omunu iyalode funfun8
Omunu iyalode pupa 8
Ewe oriji 8
Ata ijosi 16
Aolopo aofise eran elede ti agesi 16 lepo niyo
ao so sori osuka aso funfun ao se adura si ao je

ASEJE EYONU. Tete abalaye,ewe orijin,iru


,iyere niwonba,a o lo gbogbo eroja na po
pata,a o ko sinu isasun pelu eran elede a o gesi
ekiri merindilogun a o se lepo niyo,tio ba jina
tan ,a o fi iyere osun te ifa odu irete meji ,a o
pe ofore si.OLU BOYELE NI ORUKO TI ANPE
IFA 3T,AGBO KURU LORUKO TI ANPE ESU
ODARA 3T,AWODI OSAN EIYE TI FO LORU
LORUKO TI ANPE EYIN AJE,KIE EBAMI SOSI
ORO EMI L OMO L NI RERE O,KI GBOGBO
ENIYAN MA YONU SIMI O,MOTI JE ERAN EDEE
KI ARA O DEMI O ANIYAN ,A O WA DASI OBE
NAA A O JE PATAPATA.
ASEJE OSOLE
Eran elede ao ge si ekiri mesan fun okunrin
meje fun obinrin ewe orijin die ewe ola die
ewe sawerepepe die isasun tuntun kekere kan
iyere eyo merindinlogun ao lopo ao fi se eran
na je pelu epo ati iyo
IKILO Ao gbodo ba eniyan soro ti a ba nje ise
yii lo.

ASEJE GBEWA*
Eran ewure,eran aguntan,eran elede,eran
ajah,igbin opinu 3,ewe ajesesefun, ewe Emile
topo
die,ewe itiponola die,eran Erin,eran
kinnihun,eiye onbe 3,aolo gbogbo repapo pelu
ata
ijosii,iyere,aolopomon aofise awon nkan
wonyii jee,lepo niyo,odaju,aso tuntun,fila,ati
Ori enii tabi
ITE todara laotije

OGUN ASEJE OWO PUPO odaju Eran elede ao


gesi meta ao wa igbin apinu kan ao gesi meta
ewe papasan ata Ijosi epo iyo ao se laseje toba
fejina ao lo owo eyo meta tikoluju ao fi te ifa
ejiogbe ao si pe gbolohun yi si
Ayeooo 3ce Aye awowo ni ile alara,
koromilorun awowon ni ile ajero
osemigukeguke awo won nile orangun ile ila,
odifa fun orunmila oniti obare aye Aye
atuyetuyele, ifa jara odemi emi - omo - gbede
gbede gbede niro elede lorun, nijoti elede ba
pe ifa ifa adabobo, ijoti igbin bada enu dele
ojona nijifa ile, emi - omo -kinjifa owo nlala
lodo okunrin lodo obinrin lodo omode lodo
agbalagba orunmila owo eyo ni mofiwa owo
nlala wa si odore

ASIRI BIBO TO DAJU


ERAN ELEDE OOJO, IGBIN NLA KAN. A O GE
WON SI 16 - 16. GBURE, ATA IJOSI(16), IRU. A O
LO WON PAPO. A O SE ASEJE YII. TOBA JINNA,
AO SO SORI OSUKA. ADURA OHUN TI A FE. A O
JE.

Aseje Basiri
Itakun orijin, itakun ajeobale ati itakun tude lo
pelu iyere, fi se eja abori ni lepo niyo

ASEJE ASIRI BIBI TODAJU


1, Ewe tannapowo 16
Itana tannapowo 16
Ata ijosin koniye
Edo eran malu si ona 16SISE RE: Ao lo awon
eroja yi papo ao fi se edo eran malu na je pelu
epo ati iyo.
A o fi iyere osun te ejilogbe a o pe ofo yi si.
OFO RE: Sunmibare loruko ti a n pe iwo ifa,
bimilufa loruko ti a n pe iwo esu
odara, o sumo lese mejeji bare aje ni oruko ti a
n pee yin iya mi aje, tanapowo lo
powo temi wa fun mi loni, ojumo ki mo ki
alangba ma sugbe aje, gbogbo eran lo
n basiri edo, ki gbogbo omo araiye ma wa
basiri mi o. ao se adura si bi aba se fe
ao ko je.

Aseje awure todaju


Adaripon aye Kan ao ki odidi atare Kan bo
lenu ao jopo ,ao fise ekiri eran malu 21 je lepo
niyo
Note....tio ba jina ao so sori osuka aso funfun
ao se adua si dada ao koje odaju

ASEJE AWURE
Ewe ogo elewuji ao lopo ma ata ijosi merin ao
fi se saki malu ta gesi merin je lepo niyo ao je
lori
aga to fine ao si fan sori ta nba jelowo fila si
gbudo wa lori wa taba jade ao fi 10 naira
merin se
sara fun obinrin yio

ASEJE ASIRI BIBO


Ao lo re wa irin oko, epo jebo, ati iyere 16, ao
lo jebo pelu iyere papo, ao ra edo malu ao wa
ge si 16, ao wa fi irin oko yen se aseje naa,
GBOLOHUN RE:- Tete te losu nle, irawo sasa
lose elegbe leyin osu, olayinka pele o, omo
oloja roro, oke pele omo afiditina, eyi toyi taye
dina ni won pe ni koko gun, odifa fun
orunmila ni ojo ti baba nsawo lo si otu ife, won
ni baba o ni rije lotuife, won ni baba o ni rimu
lotuife,won ni baba o ni rina lotuife, won ni
baba o ni nile lori, koni leshin lekan, orunmila
binu oke mo won paaara, oni ayedina o 3×
Ayedina parada orunmila ni oto gee ona ki
dimo oloko, ona ki dimo alada, ki ema wa fi
owo nla-nla bo asiri emi LAGBAJA nitoripe
eran NLA NLA nii bo asiri edo, inu siba sibo ni
asiri ijebo ti nbo, airina, airilo, kotan loro mi
lati oni lo, ki owo nla-nla ma wole tomi wa
ASE.

ASEJE BASIRI TOSINA OWO


Edo eran malu, ao gesi 16,Ewe sesefun, Ewe
Alukerese, Epo igi jebo, Ata ijosi, Ao lo papo,
Ao fise Edo eran malu yen,lepo niyo, ti aba
setan, ao fi iyere osun te odu ifa ogbeyonu, ao
wa pe ohun re so
Ohun re: tete losule irawo sarasara niselegbe
leyin osu ,olayimika pelu omo Afegbetina 3x,
Ayidina sawo bi enitiko kofa, Ayidina sawo bi
eniko ko ogun, ohun lodifafun orunmila nijo ti
won ni ki enikeni Maya Ile awo 3x, orunmila
ni to base bi ise tohun ni ohun ko ifa ohun siko
ogun, orunmila ni Ayidina ayikuro lona,ire
awole awo, nitoripe ona kidimon oloko komale
roko, ona kidimon alada komale ye ona, ti won
bapa jebo laro todi ni Ale Asodi,gbogbo ara ni
sefunsefun fi saje owo nlanla, nisoju oloko ni
Alukerese se gbale, Ara eran ni basiri
Edo,ogbeyonu ooo jeki omo araye wafi owo
nlanla basiri emi_________ omo_______loni, Ao
se Adura si, ao wa da ifa yen sinu obe yen odi
jije.
AKIYESI: Ori oko ti won tifi roko ri daada,
lama so Aseje yen lelori, ibe naa laoti je, Ada ti
won ti lori daada ni ao mafiro obe naa lori ina

(ASEJE TAFINRI #70)


Iyere (71)
Itanna Sawerepepe( 71)
Ewe Tanapowo oojo (71)
Itanna Tannapowo (71)
#100 Tuntun Aogesi (71)
Aogun Gbogbo Erojayi Lototo Aodasinu Ikoko
Aoge Okan Malu Si (71)
Aoseje Lepo Niyo

Aséję ęyonu ti o lagbara gon


Éwé ęla męson lona męta ti ko lu rara,iyéré
męson lona męta sisé rę ao lo męson fi sé odidi
okan malu ti gé si męson ję lepo niyo laro kutu
laiti ba ęda alaye soro ti o ba di osan ao tun lo
éwé ęla ati iyéré męson mi ti a o tun fi sé ędo
malu ti a gé si męsson ję lepo niyo losan lori
ikunlę ni ihoho omoluabi,ti o bawa di alę
patapata ao lo awon éwé yi męson toku pęlu
iyéré męson toku fi sé odidi ahon malu ti a gé
si męsson ję lepo niyo lalę lori iduro ni ihoho
omoluabi lai jadé sita mo tabi ba ęnikan soro
mo.

ASEJE GBERE OWO KOMI TO MA FI UN GBA


100,000 LARIN OJO META...TI A BA NI EYONU
AWON AGBA GIDI LARA.
Ao lo wa ewe atewogba mewa,ewe
sawerepepe mewa ,ewe ola mewa ,epo
igila,iyere mewa, ao lo ra okan malu odidi kan
ao gesi mewa....ao wa se ni aseje lepo niyo,ao
se asejeyi ni irole ao wa je ni idaji ojokeji lai ti
ba enikeni so oro,ao ma se adua ti aba ti un
je...odaju

ASEJE OWO ONI HANTU "


Ao han suratul baqora kan dele, ao fo pelu omi
sibi ike kan, ao tun han suratul jinnu meje
dele, ao fo pelu omi sinu ike kan loto, ao lora
okan malu ti owo mi kan, ao ge si 16,ao wa gun
ewe ojuoro ati ewe osibata ati ewe
tannagbowo ati itanna re pelu iyere 16, ao fi
omi hantu baqora seje lepo, niyo, toba jinna,
ao so kale sori osuka aso funfun , ao se adua si,
ao je, ti abati je tan, ao mu hantu keji le mole.

Aseje Owo
Abo adie alawo meta ao pa ao ge kekeke si ona
to ba wuwa, iru iyere ata ijosi ewe ologosese
ao gun gbogbo re ao fi se adie yi lepo niyo
To ba tutu ao fi iyere osun te ifa eji ogbe ao pe
ofore si ao dasi ao koje
Arin igi oko lo longosese nti de ade tie gbogbo
ibi ti month badurosi ni kiwan ti ma de mi ni
ade owo nla nla, eji ogbe baba ifa wa gbe
alanu temi komi nibi ti mobaduro si

ASEJE TI AFINKURO NINU IDEKUN AIYE


Ao wa eran ede,ao gesi ona merindilogun,ewe
oriji die,ao lo ewe yi pelu ata ijosi,ao se lepo
niyo,pelu eran yi,ti o bati fe jina,ao wa ogede
abalaye meta,ao gesi meta meta yio je
mesan,ao wa dasi inu e lori ina,toba ti jina,ao
so sori osuka,ao se adura ohun ti atori re se ise
yi si dada,ao je,ao mu omi aiye le lori,odaju

ASEJE TAFINRI OWO TODAJU


Ao wa ewe sasamura,pelu ewe eyinbisowo,ao
lowon pelu ata ijosi mesan,ao wa fise eran etu
je lepo niyo,toba jina ao so sori osuka kan,ao je

. ASEJE ILE KIKO TODAJU


Ileke itun,ileke ifa,abere die,ileke iyun,iye agbe
meta,iye aluko meta,ikonde meta,
omonigelegele die,ewe ogo die,ao lo papo,ao
fise eyele funfun kan tia gesi ona
merindilogun je pelu omi okun ati omi
osa,lepo niyo,ao su osuka nla kan,ao so obe na
le lori,tobaje petesi lafeko,ao lo je obe yi loke
aja,sugbon toba je ile ile lafe ko,ao lo je ni ori
apoti tiko ga pupo ju

ASEJE AWURE OWO.


Eyele funfun kan ,omi okun ,omi osa ,ati omi
agbon ,iyere ati oyin igan.
A o pa eyele yii,a o gesi ona 16 , a o da omi
okun ati omi osa sinu ikoko aseje tuntun.A o lo
iyere Kuna a o da sinu re. A o fi omi meteeta
see laseje lepo niyo.
N.B .OWO IROLE NI AO SE ASEJE YII OOO,TI
BA FE SUN LALE , AO SADURA SII DAADAA , A
O KOJE LAIJE OHUNKOHUN LELORI MOO. TO
BA DI OJO KEJI KI ORUN TO YOO , A O TI MAA
RI APEERE GBIGBA ADURA.

ASEJE AWURE OWO KIA KIA


Ewe eyinbisowo, ewe aje sefunsefun, ewe
atewogba, iyere, ao lo won po, ao fa sinu
isasun tuntun, ao bu epo pupa ati iyo sinu re,
ao fi se igbin kan toba bonu daada kan je,

ASEJE ITAJA TODAJU


Ewe ekuya,ewe atewogba ao lopo pelu ata
ijosi,ao fise igbin nla meji je lepo niyo,ao se
adura si,ao koje,odaju

ASEJE ANU
Aowa eye lekeleke toni ifun ninu Aojo pelu
Atare Odidi aolo kunna aoro sibikan
Lilore. Aoma fise Ahon malu je diedie
kise dandan ki Ahon malu yenje Odidi o
Aomase lepo niyo

ASEJE AWURE OWO KIA KIA


Itana yunrunyun......itana powo ....itana
sawerepepe.....epo jebo die....iyere die...a o lo
po a o fi se edo maalu ti kowo mi.....lepo-niyo
lodin din be a o se Adura gidi siii a o je..

You might also like