You are on page 1of 2

OBIRIN TUJUKA IGBAGBO RE MU O LARADA MATIU 9 V 22

ARAKURIN ATI ARABIRIN NINU OLUWA. KI ALAFIA AYO ATI ANU KI OJE TIYIN LATI ODO OLORUN BABA WA.
AMIN !
ONI TI NSE OJO ISIMI OJUMO 11 OSHOU KEFA NINU ODOUN 2023 OJO ISIMI KINI LEYIN METALOKAN. KOKO
ORO TI IJO WA GBE KALE NI IWAJU SÒ WIPE : IGBALA NIPA IGBAGBO
KI A TO WO INU AWON ALAYE NI EKUN RERE EJE KI A GBIYANJU LATI SHALAYE AWON GBOLOHOUN
« IGBALA » ATI « IGBAGBO ». IGBALA NI ITUSILE PATAPATA ATI IYODA ABI OMINIRA TI ENIYAN RIGBA ;
IBASEPO TI IGBALA NISE PELU IJOBA OLORUN NI IYE AINIKPEKUN. OLORUN LO NI IGBALA YI TI O SI FIFUN
WA NIPASE JESU KRISTI OMO RE KANSOSO TI O WA SI AYE LATI KPARI ISE IGBALA LORI IGBI AGBELEBU. NINU
KINI ENIYAN TI RI IGBALA ?
AGBAWA LA KURO NINU ESE, KURO NINU IDAJO, KURO NINU EGBE ATI KURO NINU IBINU OLORUN
(ROMU 5 V20). LEYIN NA, BI A BA FE SO NIPA IGBAGBO : OJE IDANILOJU OHOUN TI A RETI ATI IJERI SI OHOUN
TI A KO RII (HEB 11V1). O WA LATI INU OHOUN TI A NGBO (ROMU 10V 17) TI O WIPE "NIPA GBIGBO NI
IGBAGBO TI WA, ATI GBIGBO NIPA ORO OLORUN. OLODODO YIO YE NIPA IGBAGBO LAISI IGBAGBO ENIYAN
KO LE WU OLORUN" (HEB 11 V 6)
ARAKURIN ATI ARABIRIN NINU OLUWA, IHINRERE TI A KA NI OWURU YI FIHAN WA BI JESU TI PE
MATIU, IWOSAN OBIRIN ONI ISUN EJE ATI BI O TI JI OKU OMOBIRIN JAIRU. MATIU JE AGBOWO ODE LOWO
AWON JU, FUN AWON JU WON A MA KA AWON AGBOWO ODE SI ELESE NITORI WON A MA FI ONA EBURU
KO OLA ATI ORO JO NIPA ISE YI (LUC 3 V 13). MATIU JE OGBOTARIGI NINU ISE YI, SUGBON NIGBATI O GBO
IPE TI JESU TI NSE OLUKONI ODIDE, O SI FI OHOUN GBOGBO SILE, O SI TELE JESU. AYE RE GBA IYIPADA O SI
DIRO MO JESU NINU IRIN AJO TITUN : MATIU SE AJOYO NLA NINU ILE RE O SHE AJOYOYI FUN JESU LATI BU
OLA FUN ENITI ON SE TIRE ATI NITORI O DA GBERE FUN AYE ESE ATI IGBE AYE BUBURU TI ON GBE SIWAJU
IPE YI.
ARAKURIN ATI ARABIRIN NINU OLUWA, AWON ESE 20 ATI 22 IWE YI NSE AFIHAN OBIRIN TI ONI ISUN
EJE LATI ODUN MEJILA. NI ISRAEIL, IRU ENI BE JE ENI TI A KA SI A LAIMO KO SI NI IBASEPO KAN PELU PEPE
OLUWA. OJE AILERA TI O NI AGBARA FUN OBIRIN YI, NITORI EJE YI NSUN NI OJOJUMO. BENI IKU TI WA NI
IWAJU RE. OLUGBALA NKOJA LO NI OJO YI, OBIRIN YI SI MO PE O LE WO ON SAN, O GBAGBO PE PELU JESU
OHOUN GBOGBO NI SISE, NI O SE RO NINU OKAN RE PE : "BI MO BA LE FI OWO MI KAN ISHETI ASO RE ARA
MI YIO SI DAA". ELEYI JE IGBAGBO TI O YE KORO TI A RI NINU ARABIRIN YI, PELU GBOGBO ITIJU ATI ABUKU
TI AILERA YI TI MU RII. IBAPADE KEKERE YI TO FUN OBIRIN ONI ISUN EJE YI, NITORI RE NI O SE WIPE : "EMI
KI YIO FI OWO KAN ON FUN RA RE, SUGBON ISE TI ASO RE LATI EYIN KI ENIKENI KI O MA BA MO". LOGAN
AGBARA IWOSAN JADE LARA JESU, NIPA IGBAGBO TI OBIRIN YI NI FUN OGO OLUWA. OBIRIN YI KI HA SE
AWORAN OLORUN ? GEGE BI AWON TI O SALO BA NIGBATI O GBIYANJU LATI WO ARA RE SAN PELU AWON
EWE ATI EGBO NI ORISHIRISHI. IBAPADE KANSOSO PELU JESU KRISTI O TU NI SILE O SI FUN NI NI IYE,
IDAHOUN NIPA IGBAGBO A MA FUN ENIYAN NI OKUN ATI IGBALA FUN OKAN TO NSARE. OMOBIRIN TUJUKA
IGBAGBO RE MU O LARA DAA.
ARAKURIN ATI ARABIRIN NINU OLUWA, NIGBATI OBIRIN YI NSUMO JESU, O WA NI ONA LATI LO GBA
OMODEBIRIN JAIRU SILE LOWO IKU. OMODEBIRIN YI JE OMO ODUN MEJILA, EYI TUMOSI PE A BI
OMODEBIRIN YI NIGBATI AILERA ISUN EJE BERE FUN OBIRIN ONI SUN EJE NII.
JAIRU ENITI NSE OLORI SINAGOGU, JE ENITI O FERAN OMO RE PUPO TI O SI SHIKE RE. OKAN JAIRU
GBONGBIN SUGBON ONI IGBAGBO, IDI EYI LO FI SARE LATI WA KEPE ORE OFE OLORUN, NITORI TI O MO RIRI
AGBARA LATI ORUN WA EYI TI MBE NI IKAWO JESU. NWON WA LATI WA SO FUN JAIRU PE OMOBIRIN RE KU,
SUGBON BI O TI WU KORI O MO WIPE KOSI IDIWO ABI IYATO KAN FUN JESU LATI WO ALAISAN SAN ABI LATI
JI OKU DIDE. "WA FI OWO RE LE ON YIO SI YE". EWO IRU IGBAGBO TI OKURIN YI NI. OPOLOPO ERO MBE
NINU ILE RE, AWON AFUNFERE, ATI OPOLOPO ENIYAN WON POHUN RERE EKUN. SUGBON IKU JE ON TO
MU EDUN OKAN PUPO WA. BENI O MA RI NINU AYE WA FUN AWON ORISIRISI OHUN TI A NSE NIGBATI OKU
BA KU, O MA BO IRORA TI IKU YI MU WA. SUGBON KO LE MU ITUNU TO PE YE WA. KI A SO NI PA JESU TI O
JI OKU DIDE L’ONI AYE FII NSEFE. 24 TI OYINRERE TI A KA NI OWURO YI ;
NIGBATI JESU WO INU ILE YI, O MU KI AWON ENIYAN JADE O SI FI AWON TI WON GBAGBO LATI RI
IYANU TI JESU FE SE SILE. FUN JESU, OMODEBIRIN KO KU SUGBON O SUN. NITORI EYI LO SE WA LATI JII DIDE
KURO NINU ORUN RE. JOH 11 V11 O FI IWA PELE ATI IFE OKAN RE SI ENIYAN GBOGBO FA OMOBIRIN NA NI
OWO SOKE, BENI OMODEBIRIN NA SI DIDE. ELEYI JE IGBAGBO ALAIDIYELE TI A RI NINU AYE AWON ENIYAN
MEJI YI, TI O SI FARAHAN PELU NINU AYE ABRAMU TI ARI KA NINU GENES 12 V19. ELEYI NI LATI RANWA
LOWO LATI TU BO FI IGBEKELE WA SINU OLORUN. NIGBATI OLORUN PE ABRAMU OJE IPE NA LAISHE AWAWI,
O SI JA SI IBUKUN FUN V1 ATI 2 GEN 12. ABRAMU LO SI ILU TI NSE IBUGBE AWON ENIYAN BUBURU, TI
OLURUN FUN ARA RE TI SE ILERI LATI PARUN NIGBATI AKOKO NA BA TO. SUGBON ABRAMU KO FOYA, NITORI
TI OLORUN WA PELU RE O SI FI ARA RE HAN FUN. NIGBATI ONIGBAGBO KAN BA NRIN NINU OMINIRA ATI
IBERU, OLORUN YIO FUN NI IMOLE TI YIO FI AGBARA FUN IGBAGBO RE. PAULU NIPA EPISTELI RE SI AWON
ARA ROMU 4 V 13-25 RAN WA LETI AWON IMUSE ILERI TI OLORUN SE FUN ABRAHAM. NITORI OLORUN KO
LE SAIMASE OHOUN KOHOUN TI O BA SO. ILERI FUN ABRAHAM PE ON O SE AROLE AIYE, ATI PE ON O JE
ORISUN IBUKUN, ATI BABA FUN ORILEDE PUPO. O WA SI IMUSE, EYITI A SI NGBO TITI DI ONI. ARA NINU
OLUWA, ANI LATI NI IGBAGBO KI A BA LE DI ENI IGBALA, ATI LATI RI OHUN GBOGBO GBA LOWO OLORUN
WA.
ARA LOKURIN ATI LOBIRIN, KI SE IGBAGBO PE JESU NI OMO OLORUN, ENITI O WA SI AYE LATI SE
OPOLOPO OHUN RERE FUN WA…. RARA !! SUGBON IGBAGBO NINU OLORUN, NI IGBAGBO PE JESU WA LATI
ODO OLORUN, LATI WA WA RII ATI LATI GBA WA LA. OKU NITORI ESE WA, O SI JI DIDE FUN OGO ORUKO RE.
IGBAGBO NINU JESU OLUWA, O JE IGBAGBO TI O LE SO LATI INU OKAN WA GEGE BI PAUL APOSTELI PE :
"OMO OLORUN ENITI O FE MI TI O SI FI ON TIKARARE FUN MI" GAL 2v20. NINU JOH 11v40 JESU WIPE : "BI
EYIN BA GBAGBO E O RI OGO OLORUN". NIWON IGBATI AWA LORI ILE ALAIYE, OLORUN SI TUN LE FUN WA
NI IDARIJI RE. KI A TE OWO GBA PELU IGBAGBO, IGBEKELE, ATI MIMO RIRI OLORUN TI A GBA. NITORI KIKO
OLORUN YI SILE YIO MU WA LO SINU IPARUN AYERAYE.
KI OLORUN FI ORE OFE RE YO WA KURO NINU IPARUN, KI O SI FUN WA NI IGBALA RE. AMIN !!!

You might also like