You are on page 1of 3

NEW ERA C&S CHAPEL INTERNATIONAL

IROYIN AJODUN EGBE RUTH


Date: 7th July, 2013

Oro Isaju
A fi ogo fun Olorun, Alagbara, eni ti o mo ohun gbogbo, eleda gbogbo aye ti o mu wa ri ojo oni, eyi ti a nse ajodun akoko ninu ijo yi. A fi ogo fun oruko re Ki oruko re ki o di iyin logo.

Ikini
Leyin ti a ti gbe oruko oluwa ga, o se pataki lati yin oruko oluwa lori aye awon mama wa, Mummy G.O - Reverend Prophetess (Dr) Bose Dawodu (J.P). Iranse Olorun tooto, eni ti olorun pe ti o si yan , iriju olorun, Woli ti o tayo laarin awon woli, eniyan ti olorun nba soro loju koroju , eni ti olorun ran nise ti o si n je ise naa lai se egbe . A dupe fun Ise takuntakun ati ifokansin won lori oke Kameli yii (Awon Oluka iroyin naa meteta yio wa ni ikunle) A gba ni adura wipe ki oluwa ki o tubo di eyin ati ebi yi ni Nigeria ati loke okun mu sinsin (Amin). Mama wa, a ki yin wipe e ku ise oluwa, oluwa yio so agbara di otun. Ikinni wa lo si odo gbogbo awon osise ni pepe mimo yii lati ori Pastor Ebenezer Olorunnisola, Assistant Pastor Femi Adewunmi, Evangelist Joseph Akinyemi, Rabbi Michael Aderibigbe ati Rabbi Taiwo Adebanji. A gba ni adura wipe ki oluwa ki o so agbegbe yin di nla. (Aamin) Ope wa pataki lo si odo awon baba wa ti won je oludamoran wa eyi ti n se Evangelist Busayo Olagbile fun igbiyanju won nipa ti owo,adura ati imoran lori egbe yii. A dupe gidigidi lowo yin. A si gba ni adura wipe oluwa yio gbe yin ga, yio si bukun fun yin ni gbogbo ohun ti e ba n da owo yin le (Aamin)

A ki gbogbo awon alejo ti o wa ba wa se ajodun ni oni. Adura wa ni wipe oluwa yio so gbogbo yin pada si ile onikaluku yin ni ayo ati alafia ara (Aamin)

Tani a npe ni Ruth?


Gege bi a ti ka nipa re ninu iwe mimo, ninu iwe Ruth, Obinrin je oniwa rere eniyan ti ko fa seyin ni ojo idanwo. Ruth je iyawo omo Naomi eyi tin se Iyawo Elimeleki ara betlehemu ti Judah. Obinrin yii leyin iku oko re pinu lati duro ti Iya Oko re bi o ti le je wipe enikeji re ti nse Orpa pada lo si ile re. Nipa bayi, Olorun pese Oko rere fun. Nitori na, ni oni gege bi a tin se ajodun Ruth ni oni, a gba gbogbo omo egbe ati ijo lapapo ni iyanju wipe ki a se amuye iwa rere Ruth nigba ojo iponju pelu ireti wipe ohun rere yoo je ti wa ni ikeyin. A wa gba ladura wipe gbogbo awon obinrin ti won n ri idamu ninu ile oko won , nipa ajodun Ruth ti a n se yii, oluwa yio ran alafia re sinu iru ile bee (Aamin)

Ohun ti a nilo lati se


Gege bi omo egbe Ruth ati obinrin rere lapapo, o se pataki fun wa lati jere okan fun Jesu, e je ki a pinnu lokan wa lati ma wa lati tun inu ile olorun yii se gege bi a se mo wipe atunse ile olorun je ojuse obinrin. A tun ro awon iya wa lati ma gbe awon omo won wa fun Isin Shiloh ati iwe pataki fun awon omo won ni gbogbo ojo Wednesday. A tun fi akoko yi gba awon ti ko ti ni oko tabi aya niyanju lati ba oluwa pade ninu isin ologo yi ni gbogbo ojo Wednesday. Ni akoko yii, o se pataki fun gbogbo omo egbe Ruth lati se afarawe iwa rere eni ti a nje oruko mo yii lati fi je apere rere fun gbogbo awon omo ijo yii, awon ara ile wa ati awujo lapapo.

A gba ladura wipe, Anu, Ibukun ati Ojurere Olorun yoo ma to wa leyin ni gbogbo ojo aye wa (Aamin)

Ruth Obinrin Oniwa Tutu Ruth Obintin Olorire Ruth Obinrin ta se logo

Oro Ipari (Orin New Era)


New Era So mi dotun Ibanuje mi ti fo lo Gbogbo Omije mi ni Jesu nu Kuro New Era so mi dotun

You might also like