You are on page 1of 45

ORIN AKUNLEKỌ

i 11s 10s
Ẹmi l'Ọlọrun awọn to ba n sin,
L'ẹmi at'otọ ni ki wọn kunlẹ:
Iwọ ti n gb’arin awọn Kérúbù,
Jọ sunmọ wa, gba t'a ba sunmọ Ọ.
AMIN

ii Ẹmi, Ẹmi, l'Ọlọrun awọn to ba n sin Ọ o, 2ce


Ẹmi pẹlu otitọ ni ki wọn kunlẹ,
Iwọ to n gbe arin awọn Kérúbù,
Jọwọ sunmọ wa Baba.
ASẸ, AMIN O! KO SẸ

iii
1. Emi y'o gbadura s'Ọba mi Edumare)
Baba ye ko wa gba mi o e )2ce
Ọkan soso ajanaku,
Wa pẹlu mi nile Rẹ o,
Emi Ọmọ Rẹ — N ke pe Ọ, Baba wa rere.

2. Emi y'o gbadura s'Ọba mi Edumare )


Baba ma fi mi silẹ o e, )2ce
Ran mi lọwọ Olubukun,
Wa sikẹ mi nile Rẹ o,
Emi Ọmọ Rẹ n ke pe Ọ o, Baba wa rere.

3. Emi y'o gbadura s'Ọba mi Edumare )


Ma jẹ k'emi padanu o e,
Iwọ I'Ọba aiku,
Wa pade mi nile Rẹ o,
Emi Ọmọ Rẹ n ke pe Ọ o, Baba wa rere.
4. Emi y'o gbadura s'Ọba mi Edumare )
Baba wa fun mi layọ Rẹ, )2ce
Ọkan soso ajanaku,
Ye bukun mi nile Rẹ o,
Emi Ọmọ Rẹ n ke pe Ọ o, - Baba wa rere.

iv. Baba a de loni o! ) 2ce ) 2ce


Wa sure fun wa ka to lọ )
Olu Ọrun jọwọ ye ye o !
Edumare Baba a de loni o i 11s 10s

Wa sure fun wa ka to lọ
Awọn agan to wa nibi,
Jẹ ki wọn finu s'oyun,
Awọn t'o ti bimọ,
Jẹ ki wọn r'owo fi tọ wọn,
Awọn ti ko r'isẹ se,
Pese isẹ fun wọn,
Awọn t'ile n le,
Jẹ ki ile r'oju fun wọn;
Edumare dakun, dakun, dakun,
Baba Mimọ, Baba a de loni o!
Wa sure fun wa ka to lọ.
ASẸ, AMIN O! KO
SẸ

v Baba Ọrun jọwọ o — Wa ba wa pe, ) 2


Ẹmi Ọrun ye ajuba Rẹ — Wa ba wa pe )
A firẹlẹ wolẹ f'Ọba to ni wa,
A dupẹ gbogbo ore ta ti ri,
Gb'ọpẹ wa, gba'yin wa oni o,
A juba Rẹ - wa ba wa pe,
Baba Ọrun jọwọ o - wa ba wa pe,
Ẹmi Ọrun ye sọkalẹ o, ko wa ba wa pe.
ASẸ
vi Baba Olodumare a tún de, )
Olu Ọrun o - awa ma tun de, )2ce
Ọba to n so ohun gbogbo
Ọba to n s'ohun gbogbo
Ọba to da wa si latesi,
Ọba to n pa wa mọ,
Ọba to n pese fun wa,
Ipese alafia to ju ohun gbogbo lọ,
Ọba ikẹ Igẹ,
A m'ọrẹ wa fun Ọ o — Ọba Eledumare,
Ye - Wa gb'ore wa o,
Baba Mimọ.
ASẸ

vii Fi rẹlẹ wolẹ f' Oluwa Ọba Aiku )


Iwọ la o ma sin titi aye wa )2ce
Oluwa dakun jare dabo bo gbogbo wa
Ti a fi Ọ s'apata igbala wa,
Loni o bukun wa ka m'ayọ re ile o!
Ka ma'yọ re'le o (2ce)
Loni o bukun wa ka m'ayọ re'le o.
ASẸ, AMIN O! KO SẸ

viii 1. Jẹki 'sin wa oni le jẹ 'tẹwọgba o,


Bukun 'sin wa oni,
Wa fun wa layọ.
Egbe: Fun wa l'Ẹmi re, )2ce
Fun wa l'Ẹmi Rẹ o Baba,
Ka le jẹ tirẹ.

2. Dari ẹsẹ wa ji wa loni Baba,


Bukun 'sin wa oni — Wa fun wa layọ.
Egbe: Fun wa l'Ẹmi rẹ,

3. Gba'yin gb'ore wa t'a mu wa fun Ọ o,


Wa mi si wa Baba — ka mayọ rele.
Egbe: Fun wa l'Ẹmi rẹ,
ASẸ

ix Edumare a wolẹ fun Ọ loni )


Wa ba wa pe o — Ẹlẹru niyin, )2ce
Baba Rere,
Sure fun wa Baba — ran wa lọwọ,
Ran Ogun Ọrun Olubukun sọkalẹ,
Ki Ẹmi rẹ ba wa pe,
Wa da wa lare — Ẹlẹruniyin,
Baba rere.
ASẸ

x Jehovah mi si wa lọjọ oni Baba,


A wolẹ fun Ọ! wa, wa, wa,
Ẹmi Ọrun jare wa mi si wa loni o o o e,
Jọwọ ye, gba wa o!
Lọwọ aye, lọwọ ọta, lọwọ iku ojiji,
Tẹmbẹlẹkun ọmọ araye gbawa o !
A dupẹ Edumare:
Jehovah mi si wa l'ọjọ oni
Baba
A kunlẹ fun Ọ o wa, wa, wa,
Ẹmi ọrun jare wa mi si wa,
Loni o o o e.
ASẸ, AMIN O, KO SẸ

xi Ye - Oluwa a de ) 2ce
Awa de o lati yin Ọ fun Ọjọ oni.
Ye Oluwa a de,
Awa de o lati juba Edumare Ọba to da wa,
Ye - Oluwa a de,
Dariji wa o — Baba wa,
Ma jẹ ka r'ohun asise.
Ye — Oluwa a de,
Awa de o lati juba Mose Orimọlade,
Ye — Oluwa a de,
Awa de o — Baba wa,
Awa Ọmọ Rẹ de o,
A tun de, a wa gbe Ọ larugẹ;
Ma jẹ k'oju ti wa o,
Ye — Oluwa ade,
Awa de o lati juba Rẹ o,
K'ọjọ oni le yẹ wa,
B'ọmọde ba juba Baba rẹ — aye a yẹ,
Jẹ k'ọjọ oni le yẹ wa o,
Edumare atobiju Baba.
.................INTERLUDE......................

Ẹfọran owu ki de’na dena,


Ma jẹ ka ri d'ènà o,
Bo ti wu ki òsèré pọ to,
Ta 'gogo ni yoo leke,
Jẹ k'ọjọ oni le yẹ wa o,
Edumare atobiju Baba
.................INTERLUDE......................

Ẹni ti o ba se lore — lyẹn a f'ọpẹ fun Ọ,


Ẹni ti o ba se lore — lyẹn ki ri itiju,
Jẹ k'ọjọ oni le yẹ wa o,
Edumare atobiju Baba.
ASẸ
xii Tune: Ẹlẹsẹ wa sọdọ Jesu — 8. 7

Olugbala gbadura wa,


B'a ti fi 'gbagbọ kunlẹ
Jọ si ferese anu Rẹ
Ko da'bukun sori wa
Ko de Oluwa a mbẹ Ọ
Jẹ k'ojo ibukun de o
Awa n duro, awa n duro,
M'ọkan gbogbo wa sọji.
AMIN

xiii Tune: Igbagbọ mi wo Ọ - 6s. 4s.

Ọlọrun Baba wa,


Masai wa sarin
F'ara han wa
Ka sin Ọ bo ti tọ
Ka sin Ọ bo ti yẹ
Jẹ ki'sin wa le jẹ
Isin ọwọ.
AMIN

xiv Oluwa awa de, kabiyesi Ọba wa


Ẹlẹru ni yin, dariji wa
Baba wa
Ta l'a ni t'a gbojule
Ta la ni ta fẹhin ti,
Bikose Iwọ Ọlọrun wa,
Ẹlẹru ni yin dariji wa o.
ASẸ
xv Jah L'oke a de o, a tun de
o, a tun de t'aroye wa )
A de o t'ọwọ t'ọwọ )2ce
Messiah ye wa gbọ )
Wa ba wa pe ninu wakati
yi o Ọba Ọlọla
Olupese Ọba pataki jọwọ ye
awa mbẹ Ọ o.
Jah l'oke a de o, a tun de
t'aroye wa,
Ade o tẹrutẹru,
Oyigiyigi ye wa gbọ.
ASẸ, AMIN O, KO SẸ.

xvi Wa! Wa ba wa gbe O ) 2ce


Ninu ile Rẹ Oluwa )
Awa n jọsin a tun n sọpe
Ọpẹ ore o
Eleti gbaroye gbọ o
Ọba oke mi si wa o (2ce)
Pawa mọ lọwọ tẹmbẹlẹkun inu aye
Ka se 'fẹ Oluwa b'awọn ara igbani
Ọba to gbọ ti Mose
Wa gbọ tiwa Oluwa
ASẸ, AMIN O KO SẸ.

xvii Tune: Wa ba mi gbe Alẹ fẹrẹ lẹ tan 10s.

1. Ẹ wa s'apakan, k'ẹ sinmi diẹ.


Mo mọ arẹ ati wahala yin,
Ẹ nu òógun oju yin nù kuro,
K'ẹ tun gb'agbara n'nu agbara mi.

2. Ẹ takete s'ohun adun aye,


Ẹ wa fun idapọ t'aye ko mọ,
Ẹnikan wa lọdọ Mi oun Baba,
Lọdọ Mi oun Baba ẹgbẹ yin kun.

3. Ẹ wa sọ gbogb'ohun t'ẹ se fun mi,


So t'isẹgun ati t'isubu yin.
Mo mọ b'isẹ ẹmi ti soro to,
Ade t'o dara t'on t'omije ni.

4. Ẹ wa sinmi, ajo naa jin pupọ,


Aarẹ o mu yin, ẹ o ku l'ọna
Ounjẹ iye wa nihin, ẹ wa jẹ,
Nihin l'omi iye wa, ẹ wa mu.

5. Jade lọtun lat'ọdọ Oluwa,


Ẹ pada lọ sisẹ titi sulẹ:
Ẹ ko padanu wakati t'ẹ lo
F'ẹkọ mi si, at'isinmi ọrun.
AMIN

xviii
1. Jesu, wa sarin wa,
L'agbar'Ajinde;
Jẹ k'isin wa nihin
Jẹ isin ọwọ.

2. Mi ẹmi Mimọ Rẹ,


Sinu ọkan wa;
Mu 'foya at'aro,
Kuro l'ọkan wa.

3. Bi a ti n yara lọ,
Lọna ajo wa;
K'a ma sọna f'ọrọ,
T'o j'ayeraye. AMIN
xix
1. Baba, Baba, awa wolẹ niwaju Rẹ,
Baba, Baba, tan'mọlẹ Rẹ si wa,
Baba, Baba, oungbẹ Rẹ n gbẹ ọkan wa
Ẹmi ọrun sọkalẹ sarin wa.
Egbe: Fun wa l'agbara
At'ayọ n'nu ẹmi wa
Ka le dabi awọn t'ase logo
Ti n fi harpu wura yin i niwaju Rẹ,
Pẹlu Stephen ni aya Abraham.

2. A n wo iro ẹjẹ Rẹ n san kọjá lọ,


Bi itanna wura ta se logo
Isun iwẹnumọ fun 'fiji, ẹsẹ.
Ti n san niha Jesu Olugbala.
Egbe: Fun wa l'agbara............etc.

3. Ẹmi ọrun itansan 'mọle otitọ,


Tansan 'bukun lati ila orun,
Tan saarin wa bi t'ọjọ Pentikọsti,
Jẹ ki ami Rẹ han siwaju wa.
Egbe: Fun wa l'agbara............etc. ASẸ

xx Olugbohun gbọ tiwa loni o, )


Baba rere, )2ce
Jẹ k'áyé wa dun ka le seso rere )
Ka ma m'osi ka ma tọrọ jẹ o,
Ka ma saisan — ka ma dẹni ẹyin,
Ka r'owo logba ka bimọ lemọ o,
Nibi isẹ wa ka ri igbega,
Olugbohun wa gbọ — wa gbọ o,
Gbogbo ẹbẹ ta mu wa — loni o,
........................INTERLUDE......................

Adura wa yoo goke lọ — a tẹwọ soke.


Gbogbo ẹbẹ ta mu wa — loni o,
Olugbohun gbọ tiwa loni o - Baba rere,
Jẹ k'aye wa dun ka le seso rere.
ASẸ

xxi
Olu Ọrun awa de )
Ba ti juba fun Ọ o, )2ce
Ẹmi Ọrun jọwọ — Wa gbọ ti wa, )
.....................INTERLUDE..........................

Kini ka fi tuba ẹsẹ, wa — ara o,


Irun ori iba jẹ ahọn — ko to o,
Olu idariji — dariji wa o,
.....................INTERLUDE..........................

Bi a ba jẹkọ, a darij'ewe,
Bi a ba j'ẹran a dari j'eegun o, Ọlọrun wa,
Olu idariji —dariji wa o. ASẸ

xxii Wa gbọ tiwa — Wa gbọ tiwa )


Ẹmi Mimọ o - Wa gbọ ti wa )2ce
Iwọ la wa gb'oju le,
Iwọ la wa f'ọkan tẹ,
Ẹgbẹ Séráfù wa ke pe Ọ o,
Wa gbọ ti wa,
Wa gbọ ti wa - Wa gbọ ti wa,
Ẹmi Mimọ o - Wa gbọ ti wa,
.....................INTERLUDE..........................
Ki a ma pofo — Ki a ma r'ofo o,
Ki a ma gunlẹ, ofo laye
Wa gbọ tiwa - Wa gbọ tiwa,
Ẹmi Mimọ o - Wa gbọ ti wa.

ASẸ
xxiii Awa ẹlẹsẹ de o — awa juba Baba ) 2ce
Bẹlẹjọ ba m'ẹjọ rẹ l'ẹbi,
Ko ni pẹ ni kunlẹ,
Awa jẹwọ ẹsẹ wa Baba — da wa lare,
Awa sa ti sẹ o,
Baba dakun ka wa yẹ loni i .
..........................INTERLUDE.........................

SOLO: K'iku mase pa wa, ) FULL:-


Kárùn ma gbe wa de ) Baba dákun ka
Pese fun aini wa, ) wa ye loni.

FULL: Awa jẹwọ ẹsẹ wa - Baba da wa lare,


Awa sa ti sẹ o, Baba dakun ka wa yẹ loni.
ASẸ

xxiv Awa tun de — awa tun de,


Awa juba Baba,
Awa wolẹ l'eekun wa — Olodumare,
Sọkalẹ wa — Wa ba wa pe,
Jẹ ki isin wa oni — le jẹ tẹwọgba.
SOLO: Ọpẹ Ibukun fi fun wa ) FULL:-
K'ile roju fun wa, ) Je ki isin
K'ara dẹ gbogbo wa, ) wa oni le
K'ọlọmọ ma padanu, ) jẹ tẹwọgba.
K'agan ko d'ọlọmọ )
FULL: Awa tun de — awa tun de
Awa wolẹ Baba,
Awa wolẹ l'ekun wa Olodumare,
Jẹ ki isin wa oni le jẹ tẹwọgba.
ASẸ
xxv Awa ni Baba ni igbẹjọ,
Ẹjọ wa are ni,
Nitori Jesu nikan,
Dariji wa Baba,
Nitori Jesu nikan,
Dariji wa o.
......................INTERLUDE.......................

SOLO: Ẹsẹ irọ — Ẹsẹ ole............. Dariji wa Baba,


Ẹsẹ ebu ati isọkusọ........... Dariji wa o,
Ẹsẹ iganni ati isata............ Dariji wa Baba,
Dakun o — Olu Ọrun......... Dariji wa o.

FULL: Awa ni Baba ni igbẹjọ,


Ẹjọ wa are ni,
Nitori Jesu nikan — Dariji wa-Baba,
Nitori Jesu nikan — Dariji wa o.

ASẸ
xxvi Ọlọrun Mose awa wolẹ — Eledumare,
Atobiju wa sure fun wa, (2ce)
Iwọ l'ọba ajikẹ )
Iwọ l'ọba aji pe o, ) 2ce
Arinurode Olumọran Ọkan ẹda,
A ko gbogb'ẹbẹ wa o - siwaju Rẹ.

..................INTERLUDE............. ..........

SOLO: Asẹ - Asẹ o ka ma wi FULL: Ase


Ka d'olowo o ka ma wi, “
Ka d'ọlọla o ka ma wi, “
Ka d'onile o ka ma wi, “
Ka d'ọlọmọ o ka ma wi, "
Gbogbo Ẹgbẹ o ka l'alafia “
FULL: Iwọ I'Ọba ajikẹ )
Iwọ l'Ọba ajipe, )
Arinu rode Olumọran Ọkan Ẹda,
A ko gbogbo ẹbẹ wa o — siwaju Rẹ,
Eledumare — Atobiju,
Wa sure fun wa.
ASẸ

xxvii Ni kutukutu a de o — a de o,
Aji pọn omi kutukutu owurọ,
Ki pọn omi riru,
A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura,
Baba jẹ ko yẹ wa.
........................INTERLUDE.........................

Ire olokun ni ba olokun, )


Ire ọlọsa ni ba ọlọsa )2ce
Edumare Baba — Wa sure fun wa.
........................INTERLUDE.........................

SOLO: Ibukun owo la n tọrọ,


Eledumare wa fifun wa,

FULL: Awa kanlẹkun a tẹwọ adura,


Baba jẹ ko yẹ wa.

SOLO: Ibukun Ọla la n tọrọ — Eledumare


Ibukun Ọla la n tọrọ — Eledumare,
Ibukun Ọmọ la n tọrọ — Eledumare
Alafia la n tọrọ — Eledumare
Agbara ẹmi la n tọrọ — Eledumare

FULL: A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura,


Baba jẹ ko yẹ wa,
Ni kutukutu a de o — a de o,
Aji pọn omi kutukutu owurọ,
Kii pọn omi riru,
A wa kanlẹkun — a tẹwọ adura,
Baba jẹ ko yẹ wa.
xviii
1. B'erin ji nigbo o — a ji tẹwọ
Adura soke ki Baba ye,
B'ẹfọn ji l'ọdan — a ji tẹwọ,
Adura soke ki Baba ye,
Awa t'ẹwọ adura s'olu Ọrun,
Eledumare wa gbọ tiwa
......................INTERLUDE........................

2. Oyibiripo o laye n yi,


Ko yi si rere fun wa,
Ka l'owo lọwọ — Ka bi'mọ le'mọ,
Ka kọ'le mọ'le — Ka la l'alafia,
Ki ire gbogbo ko kari wa,
K'aye mase ri wa gbese o — Ọba Mimọ,
Eledumare wa gbọ tiwa.
ASẸ

xxix
A t'ẹwọ adura — a t'ẹwọ adura,
Nile Ọlọrun — Awa t'ẹwọ adura,
Jẹwọ ẹsẹ rẹ o — Jẹwọ ẹsẹ rẹ o,
Ofin Ọlọrun ni kawa jẹwọ ẹsẹ wa,
A wolẹ adura — A wolẹ adura,
Nile Ọlọrun — awa wolẹ adura.

SOLO: Ka mase pofo laye, )


)
Kaye rọ wa lọrun, )
)
Ka b'imọ l'emọ, ) FULL:-
)
Ka tun la lafia ) ASẸ

FULL:- A tẹwọ adura — A tẹwọ adura,


Nile Ọlọrun — awa tẹwọ adura.
ASẸ

xxx
Ẹlẹru niyin awa de lorukọ Jesu )
Ọlọrun Séráfù awa wolẹ, ) 2ce
A ba buru, a tẹriba,
Awa gboju wa soke si Ọ fun aanu,
L'ọjọ oni o,
Gbogbo ẹsẹ ta ti da si Ọ,
Dariji wa Baba.
.......................INTERLUDE.....................

SOLO:- Ẹsẹ irọ ni tabi ireje — dariji wa a,


(a) Ẹsẹ ta ti sẹ lọrọ lero, dariji wa a,
(b) Ainaani ni tabi epe — dariji wa a,
(c) Ẹsẹ eeri ni tabi agbere — dariji wa o,
(d) Ẹsẹ ta ti sẹ lati ewe — dariji wa a,

CHORUS: - Oludariji ẹda o — dariji wa Baba.


FULL: A ba buru, a tẹriba,
Awa gboju wa soke si Ọ fun aanu,
L'ọjọ oni o,
Gbogbo ẹsẹ ta ti sẹ si Ọ,
Dariji wa Baba.
ASẸ
xxxi Jesu a de l'ọjọ oni o,
Isin oni d'ọwọ Rẹ o — Baba Ọrun
Dakun jọwọ — Ọlọrun Mose,
Jọwọ ma jẹ k'esu le ba wa pe.

EGBE: Ki 'bukun Rẹ- )


Ki 'bukun Rẹ ) 2ce
Ko wa ba le wa lori o e e o,
Isin oni d'ọwọ Rẹ o — Baba Ọrun.
ASẸ

xxxii Gbogbo wa t'ẹwọ adura,


Ọlọrun o saanu fun wa,
L'ọmọde l'agba awa wolẹ Messiah Baba wa,
...........................INTERLUDE............................
Bi a ba wi pe awa ko d'ẹsẹ )
A n tan 'ra wa jẹ, ) 2ce
Otitọ kan ko si ninu wa o — Ọlọrun wa,
Nitori Jesu — dariji wa Baba.
...........................INTERLUDE............................
Isin wa oni d'ọwọ Rẹ — Olu Messiah, )
Ẹbẹ wa oni d'ọwọ Rẹ — Olu Messiah, )2ce
Jẹ ko jẹ itẹwọgba — Ọlọrun Mose.
...........................INTERLUDE............................
Gbogbo wa t'ẹwọ adura,
Ọlọrun o saanu fun wa,
L'ọmọde l'agba a wa wolẹ Messiah Baba wa.
ASẸ

xxxiii
Dari ẹsẹ ji wa, )
Ọlọrun o — Ọlọrun wa )
Dari ẹsẹ ji wa, ) 2ce
Atobiju Ọlọrun wa, )

Awa mọra wa ni ẹlẹsẹ,


Abara more jẹ,
Bi akisa ẹlẹgbin o,
L'ẹsẹ ni waju Rẹ,
Ni kutukutu a bẹ Ọ o Ẹlẹruniyin,
Loni o awa wolẹ — saanu fun wa.
......................INTERLUDE......................

EGBE: Baba-Baba,
Jọwọ wa gbadura wa — Baba

SOLO: (a) K'aye wa kó loyin, )


)
(b) K'ọrọ wa ko d'ayọ ) EGBE:-
)
(c) Ki'le wa ko roju, ) Baba - Baba,
)
(d) K'ọna wa ko l'ayọ, ) gbadura wa,
) Baba.
(e) K'aboyun bi were )
)
(f) K'agan t'ọwọ bosun, )

FULL:- Ni kutukutu a bẹ Ọ o — Ẹlẹru niyin,


Loni o awa wolẹ —saanu fun wa. ASẸ

xxxiv
Baba dariji wa o, ) 2ce
Awa ẹlẹsẹ abara m'ore jẹ,
Baba dariji wa o,
Ni ti mimọ a ko mọ, )
Ni ti yiyege a ko ye'ge )2ce
Bi a ba ni ka s'ami ẹsẹ,
Ko s'ẹni to le duro ninu wa—
Baba Ọrun - Jọwọ dariji wa o.
..............................INTERLUDE.........................
Ya wa si mimọ ) 2ce
Jẹ ka le wulo fun isẹ Rẹ,
Ya wa si mimọ,
Ogun aye — Ogun Esu, ) 2ce
Ma jẹ ko de wa lọna,
Ninu ara — Ninu ẹmi,
Ma jẹ k'adura wa ni 'de na,
Ya wa si mimọ.
ASẸ

xxxv Loni awa de o lati juba Rẹ, )


Iwọ nikan lawa yoo ma sin, ) 2ce
Buruburu lawa ba,
Lati gb'ohun wa soke si Ọ, ) 2ce
Messiah,
Ogo ni fun Ọ o — iyin fun Ọ, loni
Eledua ye sọkalẹ - Wa ba wa pe,
..............................INTERLUDE.........................

SOLO: Jẹ ki oni yẹ wa o,
Ọlọjọ oni a' mbẹ Ọ,
FULL: Amin Amin ko sẹ Baba un un,
SOLO: K'aye wa dun ko l'oyin,
Ọlọjọ oni a mbẹ Ọ,
FULL: Amin ko sẹ Baba un un,
SOLO: K'aboyun bi tibi tire,
K'awọn agan d'ọlọmọ,
FULL: Amin — Amin ko sẹ Baba un un,

SOLO: Awọn ti n wa'sẹ ko risẹ se,


K'Ọlọmọ ma p'adanu
FULL: Amin — Amin ko sẹ Baba un un,

Buruburu la wa ba,
Lati gb'ohun wa soke si Ọ, ) 2ce
Messiah,
Ogo ni fun Ọ o — lyin fun Ọ loni,
Eledua ye sọkalẹ — Wa ba wa pe.

xxxvi
Edumare a ke pe Ọ o l'ọjọ oni )
Baba — wa gbọ igbe awa, ) 2ce
A ke pe Ọ l'ọdun esi — o da wa lohun,
Bekolo ba ju'ba ilẹ - ilẹ a lanu fun;
Iba Rẹ l'ọjọ oni o – a juba fun Ọ o,

.........................INTERLUDE.........................

K'aboyun bi wẹrẹ — ki agan d'ọlọmọ,


K'ọlọmọ ma padanu,
Baba wa gbọ igbe awa,
Ẹmi Orin jẹ ko ba le wa — awa akọrin
Ẹmi llu ko ba le wa — awa alulu,
At'oni waasu ọjọ oni — Oluwa ko sin Ọ lọ

.........................INTERLUDE.........................

Edumare a ke pe Ọ o, l'ọjọ oni,


Baba wa gbọ igbe awa,
Ni ipari isin ọjọ oni o,
Ka mayọ rele o,
Ka mayọ rele, ) 2ce
Ni ipari isin ọjọ oni o,
Ka mayọ rele o.
ASẸ

xxxvii
1. Gba mi Baba gba mi dakun ye, )
Gba mi Baba gba mi dakun, ) 2ce
Ọgbagba ti n gba gbogbo ẹlẹsẹ, )2ce
Iwọ nikan sa ni mo d'ẹsẹ si Baba,
Gba mi Baba gba mi dakun ye,
Gba mi Baba gba mi dakun.

2. Mo de Baba gba mi dakun ye )


Mo de Baba gba mi dakun ) 2ce
Ọmọ oninakuna de mo de, )2ce
Emi ko tun r'ẹni sa tọ mọ ye Baba,
Iwọ l'apata Igbala mi,
Mo de Baba gba mi dakun.
ASẸ

xxxviii
Tọwọtọwọ la wolẹ f'Ọlọrun Ọrun,
A ti mọ dajudaju pe,
B'ekolo ba juba ilẹ — ilẹ a lanu,
B'ọmọde juba Baba Rẹ a roko dalẹ,
Ọlọrun ifẹ a juba Rẹ o — Ki'ba sẹ,
.........................INTERLUDE......................

SOLO: A n kan lẹkun Ibukun, ) FULL:-


A n kan lẹkun owo nini, )
A n kan lẹkun ọmọ bibi, ) Wa si
A n kan lẹkun agbara ẹmi ) fun wa o.
A n kan lẹkun Ifẹ ijinlẹ )
A n kan lẹkun alafia, )

FULL: Ọlọrun Ifẹ a juba Rẹ o — ki'ba sẹ.


ASẸ
xxxix
Oluwa o, a de. Wa ba wa pe, ) 2ce
O ti seleri Oluwa,
Pe nibi t'ẹni meji tabi mẹta,
Ba ko ra wọn jọ, — ni orukọ Rẹ,
O o fi bere wọn fun wọn,
Awa de o — wa fi bere wa fun wa.
............................INTERLUDE.......................

SOLO: Ọba to gbọ ti Mose ) FULL


Ọba to gbọ ti Daniẹli ) Awa de o,
Ọba to gbọ ti Dafidi, ) wa fi bere wa fun wa.

FULL: O ti seleri Oluwa,


Pe nibi ti ẹni meji tabi mẹta,
Ba ko ra wọn jọ — ni orukọ Rẹ,
O o fi 'bere wọn fun wọn,
Awa de o — Wa fi bere wa fun wa.

ASẸ

xl
(1) Baba a tun pade l'orukọ Jesu,
A si wa tẹriba l'abẹ ẹsẹ Rẹ,
A tun wa gb'ohun wa soke si Ọ,
Lati wa aanu lati kọrin iyin.
EGBE: O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ,
A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju,
Sugbọn kikan kikan ni o si n pe,
Njẹ a de a pada wa'le Baba.

(2) A sako b'aguntan ti ko l'olusọ,


A ti nu b'aja ti ko gbohun ọdẹ,
A ti sina kuro l'ọdọ Rẹ Baba,
Dariji wa Baba si fa wa mọra.
EGBE: O se a ko yẹ...........e.t.c.
SOLO: Njẹ a de a pada wale Baba o )
FULL: Njẹ a de a pada wale Baba, )2ce

SOLO: K'awọn aboyun wa ma bi wẹrẹ,


FULL: Njẹ a de a pada wale Baba.
SOLO: K'awọn agan ko tọwọ ala B'osun,
FULL: Njẹ a de a pada wale Baba.
SOLO: K'ọmọ wa ye ka ma gbe wọn gbin mọ,
EGBE: Njẹ a de a pada wale Baba.

EGBE: O se a ko yẹ...........e.t.c.
ASẸ

xli
Awa wolẹ Baba, )
Ijọ Séráfù de loni o ) 2ce
Ọba onibu ọrẹ,
Tiwa lẹyin lati Sioni wa,
Eledumare ran wa lọwọ,
Gb'ẹbọ sisun wa loni o,
Mu gbogbo ibere wa sẹ,
..........................INTERLUDE..........................

’Gba yi la to mọ pe Oluwa ti gba wa la o,


Gbọ lati 'bugbe Rẹ — Eledumare,
..........................INTERLUDE..........................

SOLO: Ibukun owo fi fun wa,


Ibukun ọmọ fi fun wa,
Alafia fi fun wa.

CHORUS: Abiyamọ kii gbọ igbe ọmọ Rẹ,


Ko ma ta kiji,
Eledumare Baba rere wa fi,
fun wa.
FULL: Awa wolẹ Baba,
Ijọ Séráfù de loni o,
Ọba onibu ọrẹ.
ASẸ

xlii
Baba Mimọ jọwọ a de o, )
Ninu Ijọ Rẹ - Baba, ) 2ce
Olugbala sunmọ wa — Ẹlẹru niyin o, )
Olugbala sunmọ wa — Ẹlẹru niyin o,
Olugbala sunmọ wa — Ẹlẹru niyin o.
Fun wa lowo si fun wa lọmọ o,
Ninu Ijọ Rẹ o Baba,
Olugbala gbohun wa Ẹlẹru niyin o.
Fun wa lọgbọn si fun wa loye o,
Ninu Ijọ Rẹ o - Baba,
Olugbala gbohun wa — Ẹlẹru niyin o,
Olugbala gbohun wa — Ẹlẹru niyin o,
Olugbala gbohun wa — Ẹlẹru niyin o.
ASẸ

xliii
Baba - Awa ọmọ Rẹ wolẹ bi t'esi, )
Messiah o gbani Baba, )
B'ọmọde dupẹ oore ana,
A tun gba miran,
Awa s'ọpẹ o lọpọlọpọ,
Baba ọrun o se.

Gba ni Baba to laye — Eledua o,


Baba l'Ọlọrun o,
Jare wa mi si wa ye Olu ọrun o,
Kari're 'gba,
Ye wa bukun wa — lọkankan kari kari.

xliv
Gbogbo ẹsẹ ni ibaba, )
Gbogbo ẹsẹ ni ikọkọ, )
Eyi ta ti sẹ'si Ọ — Olu Ọrun o,
Atobiju dariji wa o.

.............................INTERLUDE...........................
.

Basọ ba di riri,
A o gbe falagbafọ
Bile ba dọti,
A o fọ ile wa.
Tirẹ l'aye at'ẹkun rẹ,
Baba wa mi si wa.

.............................INTERLUDE...........................
.

Baba wa mi si wa, (2ce)


Ninu adura ta o gba si Ọ,
Baba wa mi si wa.

SOLO: Ninu iwasu wa oni,


FULL: Baba wa mi si wa,
SOLO: Ninu orin ta o kọ,
FULL: Baba wa mi si wa
SOLO: Ninu isẹ isin wa oni,
FULL: Baba wa mi si wa,
SOLO: Jẹ ka m'ayọ rele,
FULL: Baba wa mi si wa,

Gbogbo ẹsẹ ni ibaba,


Gbogbo ẹsẹ ni ikọkọ,
Eyi ta ti sẹ si Ọ - Olu Ọrun o,
Atobiju - Dariji wa o.
xlv
ALL: Ọlọrun mi saanu fun mi
Gẹgẹ bi 'seun Ifẹ Rẹ
Gẹgẹ bi irọnu anu Rẹ
Nu 'rekoja mi kuro.
CHR: Dariji mi, Dariji mi )
Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce

LEAD: Wẹ mi ni awẹmọ kuro


Ninu gbogbo aisedede
F'ẹjẹ Kalfari Rẹ wẹ mi
N o funfun ju ẹgbọn owu

CHR: Dariji mi, Dariji mi )


Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce

LEAD: Daya titun si'nu mi


Gbe agbara Ẹmi wọ mi
Ki n le kọrin irapada
Kahọn mi le yin Ọ logo.

CHR: Dariji mi, Dariji mi )


Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce

LEAD: Iwọ ko bere ẹbọ ẹsẹ


Sugbọn 'robinujẹ ọkan
Mo fi Irẹlẹ tẹriba
Nibi pẹpẹ Rẹ gbọrẹ mi.

CHR:- Dariji mi, Dariji mi )


Kemi le sisẹ Rẹ dopin ) 2ce

ORIN ISỌJI ATI IDARAYA ẸMI

1. AWA ko le sai dupẹ (2)


Ore t'Ọlọrun se fun wa;
Awa ko le sai dupẹ.

2. Awa ko le sai dupẹ (2)


Fun 'dasi ati abo Rẹ;
Awa ko le sai dupẹ.

3. Awa ko le sai dupẹ (2)


Fun ipese ojojumọ;
Awa ko le sai dupẹ.

4. Awa ko le sai dupẹ (2)


Fun isẹgun lori esu;
Awa ko le sai dupẹ.

5. Awa ko le sai dupẹ (2)


F'alafia t'O ti fi fun wa;
Awa ko le sai dupẹ.

6. Awa ko le sai dupẹ (2)


Fun anu Rẹ ni ori wa;
Awa ko le sai dupẹ.

7. Awa ko le sai dupẹ (2)


Fun ifẹ ti O ni si wa;
Ti ko je a sako.

2
“Kọ mi ni iwa ati imọ rere.”
-Ps. 119:66

1. BABA wa silẹkun fun wa,


Awa Ọmọ Rẹ n jo lode,
Baba wa silẹkun fun wa?
Ẹmi agbara
Baba wa etc.

2. Ẹmi iriran,
Baba wa, etc.

3. Ẹmi igbohun,
Baba wa, etc.

4. Silẹkun, silẹkun
Baba wa, etc.

5. Ẹmi iwosan,
Baba wa, etc.

6. Ẹmi otitọ
Baba wa, etc.

7. Ẹmi igbala,
Baba wa, etc.

8. Awa Ọmọ Rẹ n jo lode,


Baba wa silẹkun fun wa.

3
TANI n fẹ Alafia? Emi n fẹ
Alafia ni Jesu fifun mi,
Lori ara mi o, Alafia Jesu fi fun mi.
Lori Aya “ “ “ ”
Lori Ọkọ “ “ “ ”
Lori Ọmọ “ “ “ ”
Lori Ẹbi “ “ “ ”
Lori Isẹ “ “ “ ”
Ninu Ile “ “ “ ”
Ninu Ijọ “ “ “ ”

4 Oju ma mọ lode
Egbe: Baba k'O ko wa yọ lọwọ ewu.
Lọwọ Ewu Oso “ “ “
Lọwọ Ewu Ajẹ “ “ “
Lọwọ Ewu Motor “ “ “
Lọwọ Ewu Kẹkẹ “ “ “
Lọwọ Ewu Ọkọ “ “ “
Lọwọ Ewu Ọta-Ile “ “ “
Lọwọ Ewu Ọta Ode “ “ “
Lọwọ Ewu gbogbo “ “ “

5 Ma kọle, ma gbe 'nu rẹ-


Ma bimọ, ma jere rẹ
Oluwa ma ma jẹ n padanu
Oluwa
Ma kọle, ma gbe 'nu rẹ
Ma bimọ, ma jere rẹ-
Oluwa ma jẹ n sasenu o
Oluwa.

6 Ẹmi esu to wa layé rẹ


Egbe: Tara sasa le jade.
Ẹmi esu to wa lọkan rẹ
Tara sasa le jade.
Irẹwẹsi ………………
Ironu………………......
Amọdi…........ lara….........
Aisan………lara…….........
Ibẹru………laya rẹ………
Ifoya………………............
Osi to wa lara rẹ- tara sasa le jade
Ibinu……………………......
Ija …………………………
Tara sasa le jade. Tara sasa le jade.

7 Adaba Mimọ, sọkalẹ wa o ko wa sọ wa di Mimọ


Oluwosan…… Sọkalẹ wa etc.
Olùgbàlà………… “ “
Olusẹgun………… “ “
Olupese “ “
Olubukun “ “
Ẹmi Mimọ “ “
Ẹmi Agbara “ “
Ẹmi Ifẹ “ “
Ẹmi Isọkan “ “
Ẹmi Suru “ “
Ẹmi Igbọran “ “
Ẹmi Anu “ “
Adaba Mimọ “ “

8 Fun mi lagbara
Egbe: Adaba Mimọ sọkalẹ wa o, fun mi lagbara,
Fun mi n’isẹgun, etc.
Fun mi n'iwosan, etc.
Fun mi n'ibukun, etc.
Fun mi n'Ayọ, etc.
Fun mi l’agbara, etc.

9 Atẹwọ ni gbalaja
Egbe: Ma fi gb'ọmọ rere

10
Ẹni n wa rere a ri rere(2)
Ọrọ mi dayọ niwaju Oluwa,
Ẹni n wa rere a ri 're,
Emi n wa rere ma ri 're (2)
Ọrọ mi dayọ niwaju Oluwa,
Emi n wa rere ma ri 're.

11 Mo r'ẹbun mi gba
Egbe: Ẹbun mi ma fi se ire.
12 Kọle s'ori Apata (2)
Ilẹ iyanrin a ba 'yanrin lọ,
Kọle s'ori Apata,
Duro l'ori Apata (2)
Ile iyanrin a ba 'yanrin lọ,
Duro l'ori Apata.

13 Ayọ Jesu fi fun wa (3) eyi daju


Egbe: 'Tori na layọ wa se kun
Isẹgun Jesu fifun wa (3)
eyi daju
Iwosan ............. eyi daju
Ipese “ “
Ibukun “ “
Alafia “ “
Abo “ “
Anu “ “
Agbara “ “

14 Oluwomisan Oluwomisan
Olugbamila Olugbamila

15 Olùgbàlà, gbadua mi
Egbe: Mo yọ, mo dupẹ o,
Oluwosan gbadura mi,
Olusẹgun gbadura mi,
Olupese “
Olubukun “
Alabo “
Oluwoye “
Ọba Ifẹ “
Jesu Kristi “

16 Ere-Ere Igbagbọ;
Ẹni ba n sin Jesu a ma r'ere je o (2)
Egbe: To ba s'emi lo ba sin Jesu
Ma ma r'ere jẹ o
To ba se'wọ lo ba sin Jesu
To ba s'ẹyin lo ba sin Jesu,
To ba s'awa lo ba sin Jesu,
Ere-Ere Igbagbọ
Ẹni ba n sin Jesu a ma r'ere jẹ o.

17 Séráfù olomi iye re o, Omi iye


Kérúbù olomi iye re o Omi iye
Ajẹ mu 'gba kan o ma ku o
Oso mu 'gba kan o ma ku o
Oso, Ajẹ mu 'gba kan o ma ku o
Ọta mu 'gba kan o ma ku o
Aboyun mu gba kan o ma bi o
Ọmọde mu gba kan o ma ye o
Agan mu gba kan o ma yun o
Alaisan mu gba kan o ma san o
Arọ mu gba kan o ma rin o
Afọju mu gba kan o ma riran o
Aditi mu gba kan o ma gboran o
Odi mu gba kan o ma sọrọ o
Adẹtẹ mu gba kan o ma mo o
Oku mu gba kan o ma jinde o
Alairise mu gba kan o ma rise o
Alaini mu gba kan o ma ni o
Talaka mu gba kan o ma rije o
Iye, Iye, Iye re o, omi Iye
Jesu olomi Iye re o, etc.

18 K'ọmọde mo pe wa k'akoko to kọja,


Egbe: Olubukun ti de loni lati wa bukun wa
K'ọkunrin mọpẹ wa, k'akoko to kọja.
K'obinrin mọpẹ wa, k'akoko to kọja,
Olubukun ti de loni, et.c.

19
1. Gbogbo Isẹ Oluwa, f'ibukun f'Oluwa
Orun ati osupa, ẹ f'ibukun f'Oluwa
Oke ati ile, ẹ f'ibukun f'Oluwa
K'ẹ yin kẹ si ma gbega titi lai.

2. Ẹyin Ẹgbẹ Kérúbù, ẹ f'ibukun f'Oluwa,


Ẹyin Serafu, ẹ f'ibukun f'Oluwa
Ọmọ-lẹhin Jesu, ẹ f' ibukun f' Oluwa,
K'ẹ yin kẹ si ma gbega titi lai

3. Gbogbo ẹgbẹ Ijọ f'ibukun f'Oluwa,


Ẹyin Igbimọ f'ibukun f'Oluwa
Ẹyin Alagba f'ibukun f'Oluwa,
K'ẹyin kẹ si ma gbe ga titi lai.

4. Keferi, Imale, ẹ f'ibukun f'Oluwa,


Gbogbo Onigbagbọ, ẹ f'ibukun f'Oluwa,
Gbogbo Ẹgbẹ Seraf' ẹ f'ibukun f'Oluwa
K'ẹyin kẹ si ma gbega titi lai.

5. Ẹ f'Ogo fun Baba ẹyin Ẹgbẹ Séráfù,


Ẹ f'ogo fun Ọmọ Ẹgbẹ Kérúbù,
F'ogo f'Ẹmi Mimọ gbogbo Ijọ Ọlọrun,
K'ẹ yin kẹ si ma gbega titi lai.

20 Ẹ fo s'oke fun Baba


Ẹ fo s'oke fun Ọmọ
Ẹ fo s'oke fun Ẹmi Mimọ
Ẹ fo s'oke fun Mẹtalọkan
Ẹ patẹwọ “ etc.
Ẹ bu s'ayọ “ ”
Kọrin soke “ “
Ẹ dọbalẹ “ “
Ẹ fi iyin “ “
Ẹ fi ogo “ “
Fori kanlẹ “ “
Ẹ gbadura si Baba
“ “ Ọmọ
“ “ Ẹmi Mimọ
“ “ Mẹtalọkan.

21 Abọ re o Jesu,
A jisẹ t'O ran wa,
Abọ re o Jesu

22 Igi Eleso jingbinni (2)


Séráfù yẹ wa o
Igi eleso jingbinni,
Igi eleso jingbinni (2)
Kérúbù yẹ wa o,
Igi eleso jingbinni.

23
1. Ma b'Oluwa sowo pọ (2)
N ko ni padanu,
Ma b'Oluwa sowo pọ,
Ma ba Jesu sowo pọ,
K'emi le r'ere jẹ
Ma ba Jesu sowo pọ,
Ma nawo mi f'Olùgbàlà.

2. Ma ba Jesu sowo pọ,


K'emi le r'ere jẹ,
Ma ba Jesu sowo pọ,
Ma na 'wo mi f'Olùgbàlà (2)
N ko ni padanu,
Ma nawo mi f'Olùgbàlà.

24 Michaeli ba wa l'esu lọ (2)


Patapata o,
Gabrieli sure fun wa
Raphaeli sure fun wa
Patapata o,
Raphaeli sure fun wa o.
Urieli sure fun wa (2)
Patapata o
Urieli sure fun wa o

25 Séráfù yoo ma dun-ko ni kan


Yoo ma dun,
Kérúbù yoo ma dun ………..
Ọmọ la o ma gbe jo…………
Asọ la o ma ri ro…………….
Owo la o ma ri na…………...
Inu wa yoo ma dun…………..
Yoo ma dun………………….

26 Irẹwẹsi jade lọkan mi (2)


Mi o ni fi ọ se
Irẹwẹsi jade lọkan mi.

27 Baba n gbe'nu mi
Ọmọ n gbe'nu mi
Ẹmi Mimọ ti sọkalẹ,
Baba n gbe'nu mi,
Ọmọ n gbe'nu mi.
Pa'na Esu, pa'na ẹsẹ, etc.
Ran mi lọwọ, ti mi lehin,
Ran sẹgun fun mi, Gbe mi nija, etc.
“ Mu isẹ kuro lara mi,
“ F'ọkan ile balẹ fun mi,
“ Tani mo ni layé lọrun, bi ko se Iwọ, et c.
“ Tan 'mọlẹ si okunkun mi, etc.
“ Gbe ibi kuro lori mi, etc.
“ Da mi si tile-tọna mi, etc.
“ Fire fun mi, fayọ fun mi,
“ Ma yọ mi kuro l'ẹgbẹ yi
Jẹ k'emi lẹsẹ aseye l'ẹgbẹ yi
Ẹmi Mimọ ti ba le mi.

28 Ki l'Orukọ Rẹ, Iyanu Iyanu (2)


O n la'ju Afọju, Iyanu Iyanu (2)
O n ji oku dide, “ “
O n gb'ayarọ dide “ “
O n wo alaisan “ “
O n pese f'alaini “ “
O n s'anu Igbekun “ “
O n da onde silẹ “ “
O n sẹgun ọta wa “ “
Ki l'Orukọ Rẹ.
AMIN
29 “Ti Oluwa ni ile.” - Ps. 24:1
Psalm 24 Chant. No. 11

1. Ti Oluwa nile ati ẹkun inu rẹ, ayé ati awọn ti o


Tẹdo sinu rẹ – Nitori ti o fi
Idi re sọlẹ lori okun o si gbe
Kalẹ lori awọn isan omi.

2. Tani yoo gun ori oke


Oluwa lo? tabi tani yoo
Duro nibi Mimọ rẹ--
Ẹni ti o ni ọwọ Mimọ
Ati aya funfun; ẹni ti ko
Gbe ọkan rẹ soke si asan,
Ti ko si bura ẹtan.

3. Oun ni yoo ri ibukun gba


Lọwọ Oluwa, ati ododo
Lọwọ Ọlọrun igbala rẹ,
Eyi ni iran awọn ti n se afẹri
Rẹ ti n se afẹri oju rẹ
Jakobu.

4. Ẹ gbe ori yin soke ẹyin


Ẹnu ọna, ki a si gbe yin
Soke ẹyin ilẹkun ayérayé:
Ọba ogo yoo si wọ inu le lọ.
Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara,
Oluwa ti o l'agbara ni ogun.

5. Ẹ gbe ori yin soke ẹyin


Ẹnu ọna, ani ki ẹ gbe wọn
Soke ẹyin ilẹkun ayérayé:
Ọba ogo yoo wọ, inu ile lọ
Tani Ọba ogo yi?
Oluwa awọn ọmọ ogun, oun na ni Ọba Ogo.
AMIN

30 “Ẹ ma yin Oluwa! Ẹ ma yin.”


- Ps. 113:1

1. Ẹ F'ỌPẸ f'iyin fun


Oluwa awọn Oluwa
Anu Rẹ duro lailai
Egbe: Ẹ f'ọpẹ f'iyin fun Ọlọrun
Ọba t'o da wa
Anu rẹ duro lailai.

2. Ẹ f'ọpẹ f'iyin fun


Ọlọrun awọn Ọlọrun,
Anu Rẹ duro lailai

3. O s'ohun iyanu nla,


O f'ọgbọn da ọrun o;
Anu Rẹ duro lailai
4. O tẹ itẹ l'or' omi,
O da awọn imọlẹ nla o;
Anu Rẹ duro lailai

5. O f'Orun jọba ọsan,


Osupa at' Irawọ,
Awọn lo fi jọba oru o;
Anu Rẹ duro lailai

6. O kolu awọn ara Egypt,


O si p'awọn akọbi wọn o,
Anu Rẹ duro lailai

7. Ọwọ agbara nla,


Pẹlu apa nina l'O fi mu
Israel jade kuro l'oko ẹru o;
Anu Rẹ duro lailai

8. O sisẹ iyanu nla,


Okun pupa pin si meji,
Israel rekọja o,
Anu Rẹ duro lailai

9. Farao at'ogun rẹ
N lepa Israeli bo o,
Wọn sure wọ'nu okun.
Okun pupa subu lu wọn
Israeli ti rekoja o,
Anu Rẹ duro lailai

10. O sin Israeli l'aginju ja,


O kọlu awọn Ọba olokiki,
Sihoni Ọba Amori,
Ogun Ọba Basari
Tẹriba f'ogun Ọlọrun.

11. O pin ilẹ ajeji fun


Israeli ni ini mi o
Anu Rẹ duro lailai

12. O ranti wa n'iwa 'rẹlẹ,


O si da wa nide,
Lọwọ gbogbo ọta o.

13. O f'Ounjẹ fun gbogbo ẹda,


Ki l'awa iba f'Ọlọrun
Ju ka f'ọpẹ at' iyin fun Ọ o
Anu Rẹ duro lailai
Egbe: Ẹ f'ọpẹ f'iyin fun Ọlọrun
Ọba t'o da wa,
Nitor' anu Rẹ duro lailai,
Ẹ ho ye, Ẹ ho f'ayọ,
Nitor' anu Rẹ duro lailai.
AMIN
31 L. M.
YIN Ọlọrun, ibu ọrẹ,
Ẹ yin, ẹyin ẹda ayé,
Ẹ yin, ẹyin ẹda ọrun,
Yin Baba, Ọmọ, oun Ẹmi.
AMIN

32 C.M.
Fun Baba, Ọmọ, at'Ẹmi,
Ọlọrun t'awa n sin:
L'ogo wa bi ti igbani,
Ati titi lailai.

33 D.C.M.
Ẹ mu ẹbọ iyin wa fun,
Ọlọrun Olore:
Ko to rara fun Ọba wa,
Bẹ l'awa le se mọ!
Ogo fun Ọ, Mẹtalọkan,
Ọlọrun ti a n sin,
Bi t'igbani, bẹ nisinyi,
Bẹni titi lai.
AMIN

34 S.M.
Si Baba, at'Ọmọ,
At'Ẹmi ibukun,
S'Ẹni Mẹtalọkan soso,
L'a n kọrin 'yin lailai
AMIN

35 D.S.M.
Iyin bi t'igbani,
Iyin bi t'isin yii,
Iyin titi ainipẹkun,
L'ẹjẹ wa f'Ọlọrun;
Ẹni t'ogun ọrun,
At' awọn mimọ n sin;
Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ ,
L'ogo wa fun lailai
AMIN

36 6. 8s.
Iyin at'ẹyẹ ailopin,
Fun Baba Olodumare,
Ogo f'Ọmọ, Olùgbàlà,
To ku fun irapada;
Iyin bakan na ni fun Ọ,
Olutunu Ayérayé.
AMIN

37
Yin Ọlọrun ni ogo,
Ẹ yin labẹ ọrun;
Ẹ yin, ọm' ogun ọrun,
Baba, Ọmọ, at'Ẹmi.
AMIN

38 6s. 7s.
Baba, Ọmọ, at' Ẹmi,
Ọlọrun Mẹtalọkan,
Jẹ k'a se 'fẹ Rẹ layé,
Bi ogun ọrun ti n se!
K'ẹda gbogbo f'iyin fun;
Ọba ọrun at'ayé.
AMIN
39 7s.
Baba, Orisun 'mọlẹ,
Ọlọgbọn at'Olore;
Ọmọ t'O sọkalẹ wa,
Ba wa gbe, Emmanuel;
Ẹmi Adaba ọrun,
Olutunu, Olufẹ:
Iwọ l'awa n yin wi pé,
Mimọ, Mimọ, Mimọ lai.
AMIN

40 8s. 7s.
Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ ,
Ọlọrun Mẹtalọkan;
Iyin, ẹyẹ fun Ọ titi,
Ayé ti ko nipẹkun.
AMIN

41 8.7.4.
Yin Baba t'O gunwa lọrun!
Yin Ọmọ Ayérayé;
Yin Ẹmi t'a fun wa lọfẹ;
Yin Mẹtalọkan Mimọ;
Halleluyah!
Ayé ti ko nipẹkun.
AMIN

42 10s
Iyin at'ogo gbogbo fun Baba,
At' Ọmọ, at'Ẹmi Mẹtalọkan;
Bakan na lana, loni, ati lai,
Ni Iwọ Ọlọrun Ayérayé.
AMIN

43 7s. 6s.
Baba, Ologo lailai,
Ọmọ, Ayérayé,
Ẹmi Asẹgun gbogbo;
Mẹtalọkan Mimọ.
Ọlọrun Igbala wa,
T'ayé at'ọrun mbọ,
K'iyin, ogo, at'ẹyẹ
Jẹ Tirẹ titi lai.
AMIN

44 6s. 4s
Ẹ f'iyin fun Baba,
At'Ọmọ, oun Ẹmi,
Mẹtalọkan,
Gẹgẹ b'Oun ti wa ri,
Bẹni y'o si ma ri;
K'ẹni gbogbo buyin,
Layé, lọrun.
AMIN

45 8s
Ogo, ọla, iyin, ipa,
Ni f'Ọdaguntan titi lai:
Jesu Kristi l'Oludande wa,
Halleluya, yin Oluwa.
AMIN

46 C.M.
Emi gbagbọ, em'o gbagbọ
Pe, Jesu ku fun mi,
O t'ejẹ lor' agbelebu,
Lati yọ mi n n'ẹsẹ.
AMIN
47 S.M.
Baba, a f'ara wa,
S'isọ Rẹ l'alẹ yi;
Dabobo wa, k' O pa wa mọ,
Tit' ilẹ o fi mọ. AMIN

48 Jesu Olore O ………………….. Olore


Mimọ Mimọ Olore O …………. Olore
Ore to semi n ó ni gbagbe……… Olore
Ma fijo san die fun u …………. Olore
Ma f'ọyaya san diẹ fun u………. Olore
Ma f'ẹrin san diẹ fun u………….. Olore
Ma fatẹwọ san diẹ fun u ………… Olore
Ma fo soke san diẹ fun u …………. Olore
Ma dọbalẹ san diẹ fun u ………….. Olore
Olore Olore temi………………….. Olore

49 “Emi yoo si se ariya ni Jerusalem.” - Isa. 65: 19


1. Jerusalemu (3ce) ibi ayọ
2. Awọn Angeli “ wọn fo yika,
3. Awọn Séráfù “ wọn fo yika,
4. Awọn Kérúbù “ wọn n fo yika,
5. Mo ti ri gbala lọdọ Jesu
6. Ẹlẹsẹ e wa (3ce) sọdọ Jesu
7. Keferi ẹ wa “ “ “
8. Abọgi ẹ wa “ “ “
9. Ajẹ ko nipa “ “ “
10. Oso ko nipa “ “ “
11. Ẹgbẹ Akọrin t'esu mọlẹ
12. Ẹgbẹ Bibeli “ “

PSALMU 24
1. Ti Olúwa ni ilẹ ati ẹkun rẹ: ayé ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ.
2. Nitori ti o fi idi rẹ sọlẹ lori okun, o si gbe e kalẹ lori awọn isan-omi.
3. Ta ni yio gun ori oke Olúwa lọ? Tabi tani yio duro ni ibi mimọ rẹ?
4. Ẹni ti o ni ọwọ mimọ, ati aya funfun: ẹni ti ko gbe ọkan rẹ soke si asan, ti ko
si bura ẹtan.
5. Oun ni yio ri ibukun gba lọwọ Olúwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun Igbala rẹ
6. Eyi ni iran awọn ti n se aferi rẹ, ti n se afẹri oju rẹ, Ọlọrun Jakobu.
7. Ẹ gbe ori yin soke, ẹyin ẹnu-ọna; ki a si gbe yin soke, ẹyin ilẹkun ayérayé: Ọba
Ogo yio si wọ inu ile lọ.
8. Ta ni Ọba ogo yi? Olúwa ti o le, ti o si lagbara, Olúwa ti o lagbara ni ogun.
9. Ẹ gbe ori yin soke, ẹyin ẹnu-ọna; ki ẹ gbe wọn soke, ẹyin ilẹkun ayérayé: Ọba
ogo yio si wọ inu ile lọ.
10. Ta ni Ọba Ogo yi? Olúwa awọn ọmọ-ogun; oun na ni Ọba ogo.

PSALMU 32
1. Ibukun ni fun ẹni ti a dari irekọja rẹ ji, ti a si bo ẹsẹ rẹ mọlẹ
2. Ibukun ni fun ọkunrin na ẹni ti Olúwa ko ka ẹsẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹni ti
ẹtan ko si.
3. Nigba ti mo dakẹ, egungun mi di gbigbo, nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ.
4. Nitori ni ọsan ati ni oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara emi ara mi si dabi ọda-ẹrun
5. Emi jẹwọ ẹsẹ mi fun ọ, ati ẹsẹ mi ni emi ko si fi pamọ, Emi wi pé, emi o jẹwọ
irekọja mi fun Olúwa; iwọ si dari ẹbi ẹsẹ mi ji.
6. Nitori idi eyi ni olukuluku ẹni iwa-bi-Ọlọrun; yio ma gbadura si o ni igba ti a
le ri ọ: nitotọ ninu isan-omi nla, wọn ki yio sunmọ ọdọ rẹ.
7. Iwọ, ni ibi ipamọ mi: iwọ o pa mi mọ kuro ninu isẹ: iwọ o fi orin igbala yi mi
ka kiri.
8. Emi o fi ẹsẹ rẹ le ọna, emi o si kọ ọ ni ọna ti iwọ o rin: emi o ma fi oju mi tọ

9. Ki ẹyin ki o mase dabi ẹsin tabi ibaka, ti ko ni iye ninu: ẹnu ẹni ti a ko le se
aifi ijanu bọ, ki wọn ki o ma ba sunmọ ọ.
10. Ọpọ ikanu ni yio wa fun eniyan buburu: sugbọn ẹni ti o ba gbẹkẹle Olúwa, anu
ni yio yi i ka kari.
11. Ki inu yin ki o dun ni ti Olúwa, ki ẹ si ma yọ, ẹyin olododo; ki ẹ si ma kọrin
fun ayọ, gbogbo ẹyin ti ọkan yin duro sinsin.

PSALMU 51
1. Ọlọrun, saanu fun mi, gẹgẹ bi iseun ifẹ rẹ: gẹgẹ bi ọpọ anu rẹ, nu irekọja mi
nu kuro.
2. Wẹ mi ni awẹmọ kuro ninu aisedede mi, ki o si wẹ mi nu kuro ninu ẹsẹ mi.
3. Nitori ti mo jẹwọ irekọja mi: nigba gbogbo ni ẹsẹ mi si mbẹ niwaju mi:
4. Iwọ, iwọ nikansoso ni mo sẹ si, ti mo se buburu yi niwaju rẹ: ki a le da ọ
lare nigba ti iwọ ba n sọrọ, ki ara rẹ ki o le mọ, nigba ti iwọ ba n se idajọ.
5. Kiyesi, ninu aisedede ni a gbe bi mi: ati ninu ẹsẹ ni iya mi si loyun mi.
6. Kiyesi, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ikọkọ ni iwọ o mu mi mọ ọgbọn.
7. Fi ewe hisopu fọ mi, emi o si mọ: wẹ mi, emi o si fun ju ẹgbọn owu lọ.
8. Mu mi gbọ ayọ ati inu didun, ki awọn egungun ti iwọ ti sẹ ki o le ma yọ.
9. Pa oju rẹ mọ kuro lara ẹsẹ mi, ki iwọ ki o si nu gbogbo aisedede mi nu kuro
10. Da aya titun sinu mi, Ọlọrun: ki o si tun ọkan didurosin-sin se sinu mi.
11. Mase sa mi ti kuro niwaju rẹ: ki o ma si se gba Ẹmi Mimọ rẹ lọwọ mi.
12. Mu ayọ igbala rẹ pada tọ mi wa; ki o si fi ẹmi omnira rẹ gbe mi duro.
13. Nigba na ni emi o ma kọ awọn olurekoja ni ọna rẹ: awọn ẹlẹsẹ yio si ma yi pada
si ọ.
14. Ọlọrun, gba mi lọwọ ẹbi ẹjẹ, iwọ Ọlọrun igbala mi, ahọn mi yio si ma kọrin
ododo rẹ kikan
15. Olúwa, iwọ si mi ni ete: ẹnu mi yio si ma fi iyin rẹ han.
16. Nitori iwọ ko fẹ ẹbo, ti emi iba ru u: inu rẹ ko dun si ọrẹ ẹbọ sisun.
17. Ẹbọ Ọlọrun ni irobinujẹ ọkan: irobinujẹ ati irora aya, Ọlọrun, oun ni iwọ ki
yio gan;
18. Se rere ni didun inu rẹ si Sioni: iwọ mọ odi Jerusalẹmu.
19. Nigba na ni inu rẹ yio dun si ẹbọ ododo: pẹlu ọrẹ-ẹbọ sisun ati ọtọtọ ọrẹ-ẹbọ
sisun: nigba na ni wọn o fi akọ-malu rubọ lori pẹpẹ rẹ.

PSALMU 99
1. Olúwa, jọba: jẹ ki awọn eniyan ki o wariri, o joko lori awọn Kérúbù; ki ayé ki o
ta gbọngbọn.
2. Olúwa to bi ni Sioni: o si ga ju gbogbo Orile-ede lọ
3. Ki wọn ki o yin orukọ rẹ ti o tobi, ti o si ni ẹru; mimọ ni oun.
4. Agbara Ọba fẹ idajọ pẹlu: iwọ fi idi aisegbe mulẹ; iwọ n se idajọ ati ododo ni
Jakọbu.
5. Ẹ gbe Olúwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ: mimọ ni oun.
6. Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ, ati Samueli ninu awọn ti n pe orukọ rẹ: wọn
ke pe Olúwa, o si da wọn lohun.
7. O ba wọn sọrọ ninu ọwọn awọsanma: wọn pa ẹri rẹ mọ ati ilana ti o fifun wọn.
8. Iwọ da wọn lohun, Olúwa Ọlọrun wa: iwọ ni Ọlọrun ti o dariji wọn, bi o tilẹ se
pe iwọ san ẹsan isẹ wọn.
9. Ẹ gbe Olúwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sin nibi oke mimọ rẹ; nitori mimọ ni Olúwa
Ọlọrun wa.

PSALMU 116
1. Emi fẹ Olúwa nitori ti o gbọ ohun mi ati ẹbẹ mi.
2. Nitori o de ẹti re si mi, nitori naa ni emi o ma ke pe e niwọn ọjọ mi.
3. Ikanu iku yi mi ka, ati irora isa-oku di mi mu; mo ri iyọnu ati ikanu.
4. Nigba naa ni mo ke pe orukọ Olúwa; Olúwa emi bẹ ọ gba ọkan mi.
5. Olore-ọfẹ ni Olúwa, ati olododo; nitotọ, alanu ni Ọlọrun wa.
6. Olúwa pa awọn alaimọkan mọ; a rẹ mi silẹ tan, o si gba mi.
7. Pada si ibi isinmi rẹ, iwọ ọkan mi; nitori ti Olúwa se ọpọlọpọ fun ọ.
8. Nitori ti iwọ ti gba ọkan mi lọwọ iku, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ
isubu.
9. Emi o ma rin niwaju Olúwa ni ilẹ alaye.
10. Emi gbagbọ, nitori na ni emi se sọ; mo ri ipọnju gidigidi.
11. Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo eniyan.
12. Ki ni emi o san fun Olúwa nitori gbogbo ore rẹ si mi?
13. Emi o mu ago igbala, emi o si ma ke pe orukọ Olúwa.
14. Emi o san ileri ifẹ mi fun Olúwa, nitoto ni oju gbogbo awọn eniyan rẹ.
15. Iyebiye ni iku awọn eniyan mimọ rẹ ni oju Olúwa.
16. Olúwa, nitoto iransẹ rẹ ni emi; iransẹ rẹ ni emi, ati ọmọ iransẹ-binrin rẹ: iwọ
ti tu ide mi.
17. Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o si ma ke pe orukọ Olúwa.
18.Emi o san ileri ifẹ mi fun Olúwa, nitotọ ni oju gbogbo awọn eniyan rẹ.
19. Ninu agbala ile Olúwa, ni arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yin Olúwa.

PSALMU 128
1. Ibukun ni fun gbogbo ẹni ti o bẹru Olúwa: ti o si n rin ni ọna rẹ.
2. Nitori ti iwọ o jẹ isẹ ọwọ rẹ: ibukun ni fun ọ: yio si dara fun ọ.
3. Obinrin rẹ yio dabi ajara rere eleso pupọ ninu ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yoo dabi igi
olifi yi tabili rẹ ka.
4. Kiyesi pe, bẹẹ ni a o busi fun ọkunrin na, ti o bẹru Olúwa.
5. Ki Olúwa ki o busi fun ọ lati Sioni wa, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu ni
ọjọ ayé rẹ gbogbo.
6. Bẹni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ; ati alafia lara Israeli.

PSALMU 130
1. Lati inu ibu wa ni emi ke pe ọ, Olúwa,
2. Olúwa, gbohun mi: jẹ ki eti rẹ ki o tẹ silẹ si ohun ẹbẹ mi.
3. Olúwa, iba se pe iwọ n sami ẹsẹ, Olúwa, tani yoo duro?
4. Nitori idariji wa lọdọ rẹ, ki a le ma bẹru rẹ.
5. Emi duro de Olúwa, ọkan mi duro, ati ninu ọrọ rẹ ni emi n se ireti.
6. Ọkan mi duro de Olúwa, ju awọn ti n sọna owurọ lọ, ani ju awọn ti n sọna owurọ
lọ.
7. Israeli, iwọ ni ireti lọdọ Olúwa: nitori pe lọdọ Olúwa ni anu wa, ati lọdọ rẹ
ni ọpọlọpọ idande wa.
8. Oun o si da Israeli nide kuro ninu ẹsẹ rẹ gbogbo.

PSALMU 133
1. Kiyesi, o ti dara o si ti dun to fun awọn ara lati ma jumọ gbe ni irẹpọ;
2. O dabi ororo iyebiye ni ori, ti o san de irugbọn, ani irugbọn Aaroni: ti o si
san si eti asọ rẹ:
3. Bi iri Hermoni ti o se sori Oke Sioni: nitori nibẹ ni Olúwa gbe pasẹ ibukun, ani
iye lailai.

ADURA OLÚWA
Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ki a bọwọ fun orukọ rẹ. Ki Ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni
ki a se ni ayé, bi wọn ti n se ni ọrun. Fun wa ni Ounjẹ Oojọ wa loni. Dari ẹsẹ wa
ji wa, bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwo: Sugbọn gba wa
lọwọ bilisi: Nitori ijọba ni tirẹ, agbara ni tirẹ, ogo ni tirẹ, lailai. AMIN

IGBAGBỌ
Mo gba Ọlọrun Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé:
Mo gba Jesu Kristi gbọ, ọmọ rẹ kansoso Olúwa wa, ẹni ti a fi Ẹmi Mimọ loyun,
ẹni ti a bi ninu Maria Wundia, ẹni ti o jiya lọwọ Pontiu Pilatu, ẹni ti a kan mọ
agbelebu, ẹni ti o ku, ti a si sin, O sọkalẹ rẹ ipo oku; Ni ijọ kẹta o tun jinde
kuro ninu oku, O re oke ọrun, O si joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba Olodumare: Nibẹ ni
yio ti wa se idajọ aye oun oku.
Mo gba Ẹmi Mimọ gbọ, Ijọ Mimọ Ọlọrun; Idapọ awọn eniyan Mimọ;
Idariji ẹsẹ, Ajinde ara ni isa oku, Ati iye ti ko nipẹkun.
AMIN

Asaju Isin: Ki Olúwa ki o pẹlu yin


Idahun: Ki o si pẹlu ẹmi rẹ.
Asaju Isin: Ẹ jẹ ki a gbadura.

PART II
FUN ỌJỌ GOOD FRIDAY ATI AJINDE

Mo gba Ọlọrun kan Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé, ati ohun gbogbo ti
a n ri ati eyi ti a ko ri.
Mo gba Olúwa kan Jesu Kristi gbọ, ọmọ bibi nikansoso ti Ọlọrun, Ti a bi lati
ọdọ Baba rẹ saaju ayé gbogbo, Ọlọrun lati inu Ọlọrun, Imọlẹ lati inu Imọlẹ, Ọlọrun
tikararẹ lati inu Ọlọrun tikararẹ, ẹni ti a bi ti a ko da, ti ise ara kan naa pẹlu
Baba; Lati ọwọ ẹni ti a ti da ohun gbogbo, Ẹni, nitori awa eniyan, ati nitori
igbala wa, ti o ti ọrun wa si ile, ẹni ti o si mu awọ ara nipa Ẹmi Mimọ lara Maria
Wundia, O si di eniyan, a si kan a mọ agbelebu pẹlu nitori wa lọwọ Pontiu Pilatu. O
jiya a si sin in. Ni ijọ kẹta o si tun jinde gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun. O si lọ soke
ọrun, O si joko lọwọ ọtun Baba. Yio si tun pada wa ti oun ti Ogo, lati se idajọ aye
ati oku: Ijọba ẹni ti ki yio nipẹkun.
Mo si gba Ẹmi Mimọ gbọ, Olúwa ati Olufunni ni iye, ẹni ti n ti ọdọ Baba ati
Ọmọ wa, pẹlu Baba ati Ọmọ ẹni ti a n sin ti a sin yin logo pọ, ẹni ti o ti ẹnu awọn
Woli sọrọ. Mo si gba Ijọ Mimọ Eniyan Ọlọrun kan ati ti awọn Aposteli gbọ. Mo jẹwọ
Baptismu kan fun imukuro ẹsẹ, emi si n reti Ajinde oku, ati iye ti mbọ wa. AMIN

DEUTERONOMI 28: 1-13


1. Yoo si se, bi iwọ ba farabalẹ gbọ ohun OLÚWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati se
asẹ rẹ gbogbo ti mo pa fun ọ ni oni, njẹ OLÚWA Ọlọrun rẹ yoo gbe ọ ga ju gbogbo
Orilẹ-ede ayé lọ:
2. Gbogbo ibukun wọnyi yio si se sori rẹ, yio si ba o, bi iwọ ba fetisi ohun OLÚWA
Ọlọrun rẹ.
3. Ibukun ni fun ọ ni ilu, ibukun ni fun ọ ni oko.
4. Ibukun ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ile rẹ, ati iru ohun ọsin rẹ, ati ibisi malu
rẹ, ati ọmọ aguntan rẹ.
5. Ibukun ni fun agbọn rẹ ati fun ọpọn-ipo-akara rẹ.
6. Ibukun ni fun ọ nigba ti iwọ ba wọle, ibukun ni fun ọ nigba ti iwọ ba jade.
7. OLÚWA yio mu awọn ọta rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlu niwaju rẹ; wọn o jade si ọ
ni ọna kan, wọn o si sa niwaju rẹ ni ọna meje.
8. OLÚWA yoo pasẹ ibukun sori rẹ ninu aka rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi
ọwọ rẹ le; oun o si bu si i fun ọ ni ilẹ na ti Ọlọrun rẹ fi fun o
9. OLÚWA yio fi idi re kale ni eniyan mimọ fun ara rẹ, bi o ti bura fun ọ, bi iwọ
ba pa asẹ OLÚWA Ọlọrun rẹ mọ, ti iwọ si rin ni ọna rẹ.
10. Gbogbo eniyan ayé yio si ri pe orukọ OLÚWA ni a fi n pe ọ; wọn o si ma
bẹru rẹ.
11. Olúwa yoo sọ ọ di pupọ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu iru ohun ọsin rẹ,
ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ile ti OLÚWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ.
12. OLUWA yoo si isura rere rẹ silẹ fun ọ, ọrun lati rọjo si ilẹ rẹ ni akoko rẹ,
ati lati busi isẹ ọwọ rẹ gbogbo: iwọ o si ma win orilẹ-ede pupọ, iwọ ki yio si
tọrọ.
13. OLÚWA yoo si fi ọ se ori, ki yoo si se iru; iwọ o si ma leke sa, iwọ ki yio si
jẹ ẹni ẹhin; bi iwọ ba fetisi asẹ OLÚWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ ni oni, lati ma
kiyesi oun ati ma se wọn.

IFIHAN 4
1. Lẹyin nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan si silẹ ni ọrun: ohun kini ti
mo gbọ bi ohun ipe ti mba mi sọrọ, ti o wi pé, Goke wa ihin, emi o si fi ohun ti
yio hu lẹhin-ọla han ọ.
2. Lojukan naa mo si wa ninu Ẹmi; si kiyesi, a tẹ itẹ kan ni ọrun, ẹnikan si
joko lori itẹ na.
3. Ẹni ti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo; osumare si ta yi itẹ na
ka, o dabi okuta smaragdu ni wiwo.
4. Yi itẹ naa ka si ni itẹ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ na mo ri awọn agba
mẹrinlelogun joko, ti a wọ ni asọ ala; ade wura si wa ni ori wọn.
5. Ati lati ibi itẹ naa ni manamana ati ara ati ohun ti jade wa: fitila ina meje si
n tan nibẹ niwaju itẹ na ti ise Ẹmi meje ti Ọlọrun
6. Ati niwaju itẹ na si ni okun bi digi, o dabi Kristali: ni arin itẹ na, ati yi
itẹ na ka, ni ẹda alaye mẹrin ti o kun fun oju niwaju ati lẹhin.
7. Ẹda kini si dabi kiniun, ẹda keji si dabi ọmọ malu, ẹda kẹta si ni oju bi ti
eniyan, ẹda kẹrin si dabi idi ti n fo.
8. Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ mẹfa, kun fun oju yika ati
ninu: wọn ko si sinmi ni ọsan ati ni oru, wi pé, Mimọ, Mimọ, Mimọ, Olúwa Ọlọrun
Olodumare, ti o ti wa, ti o si mbẹ, ti o si mbọ wa.
9. Nigba ti awọn ẹda alaye naa ba si fi ogo ati ọla ati ọpẹ fun ẹni ti o joko lori
itẹ, ti o mbẹ laye lai ati lailai.
10. Awọn agba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹni ti o joko lori itẹ, wọn a si
tẹriba fun ẹni ti mbẹ laye lai ati lailai, wọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ naa
wi pé,
11. Olúwa, iwọ ni o yẹ lati gba ogo ati ọla ati agbara: nitori pe iwọ ni o da ohun
gbogbo, ati nitori ifẹ inu re ni wọn fi wa ti a si da wọn.

ISAIAH 6
1. Ni ọdun ti Ussaiah Ọba ku, emi ri Olúwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara
soke, isẹti asọ igunwa rẹ kun tempili.
2. Awọn Séráfù duro loke rẹ; ọkọọkan wọn ni iyẹ mẹfa, o fi meji bo oju rẹ, o si fi
meji bo ẹsẹ rẹ, o si fi meji fo.
3. Ikini si ke si ekeji pe, Mimọ, mimọ, mimọ, ni Olúwa awọn ọmọ-ogun, gbogbo ayé
kun fun ogo rẹ.
4. Awọn opo ilẹkun si mi nipa ohun ẹni ti o ke, ile naa si kun fun efin.
5. Nigba naa ni mo wi pé, Egbe ni fun mi, nitori mo gbe, nitori ti mo jẹ ẹni-alaimọ
ete, mo si wa larin awọn eniyan alaimọ ete, nitori ti oju mi ti ri Ọba, Olúwa awọn
ọmọ-ogun.
6. Nigba naa ni ọkan ninu awọn Séráfù fo wa sọdọ mi, o ni ẹsẹ-ina ni ọwọ rẹ, ti o
ti fi ẹmu mu lati ori pẹpẹ wa.
7. O si fi kan mi ni ẹnu, o si wi pé, kiyesi i, eyi ti kan ete rẹ, a mu aisedede
rẹ kuro, a si fo ẹsẹ rẹ nu.
8. Emi si gbọ ohun Olúwa pẹlu wi pé, Tani emi o ran; ati tani o si lọ fun wa? Nigba
na ni emi wi pé, emi ni; ran mi.

KATEKISIMU TI IJỌ ENIYAN ỌLỌRUN

Ibere: Orukọ rẹ?


Idahun: N. tabi M.
Ibere: Tani fi orukọ yi fun ọ?
Idahun: Awọn Baba mi nipa ti Ọlọrun, ati awọn Iya mi ti Ọlọrun, ninu baptismu
mi; nipa eyi ti a so mi di ẹya ara Kristi, ọmọ Ọlọrun, ati ajogun ijọba ọrun.
Ibere: Kini awọn baba rẹ nipa ti Ọlọrun ati awọn iya rẹ nipa ti Ọlọrun se fun
ọ lakoko naa?
Idahun: Wọn se ileri, wọn si jẹjẹ ohun mẹta ni orukọ mi. Ekinni, pe emi o kọ esu
ati gbogbo isẹ rẹ silẹ, irera ati ogo asan ayé buburu yii, ati gbogbo ifẹkufẹ ẹsẹ
ara. Ekeji, pe emi o gba gbogbo otitọ igbagbọ Kristiani gbọ. Ati ẹkẹta, pe emi o
pa ifẹ mimọ Ọlọrun ati ofin rẹ mọ, emi o si ma rin ninu ọkanna ni ọjọ ayé mi
gbogbo.
Ibeere: Iwọ ko ha ro pe isẹ rẹ ni lati gbagbọ ati lati se bi wọn ti se
ileri fun
Idahun: Nitotọ; ati nipa iranlọwọ Ọlọrun emi o se bẹẹ. Emi si fi tọkan-tọkan
dupẹ lọwọ Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ti o ti pe mi si igbala yi nipa Jesu Kristi
Olùgbàlà wa. Emi si n gbadura si ọdọ Ọlọrun lati fun mi ni ore-ọfẹ rẹ, ki emi ki o
le wa titi ninu ipo naa titi de opin ayé mi.
Katekisti: Ka otitọ igbagbọ rẹ.
Idahun: Mo gba Ọlọrun Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé: Mo gba Jesu
Kristi gbọ, ọmọ rẹ kansoso Olúwa wa, ẹni ti a fi Ẹmi Mimọ loyun, ẹni ti a bi ninu
Maria Wundia, ẹni ti o jiya lọwọ Pontiu Pilatu; ẹni ti a kan mọ agbelebu. Ẹni ti o
ku ti a si sin, O sọkalẹ re ipo oku; Ni ijọ kẹta o tun jinde kuro ninu oku; O re
oke ọrun, O si joko lọwọ ọtun Ọlọrun Baba Olodumare; Nibẹ ni yio ti wa se idajo
aaye oun oku. Mo gba Ẹmi Mimọ gbọ; Ijọ Mimọ eniyan Ọlọrun; Idapọ awọn Eniyan Mimọ;
Idariji ẹsẹ; Ajinde ara ni isa oku, ati iye ti ko nipẹkun. Amin
Ibere: Kini iwọ ko ni olori ninu otitọ igbagbọ rẹ?
Idahun: Ekini, Mo kọ lati gba Ọlọrun gbọ, ẹni ti o da mi ati gbogbo ayé.
Ekeji, Lati gba Ọlọrun Ọmọ gbọ, ẹni ti o ra mi pada, ati gbogbo arayé.
Eketa, Lati gba Ọlọrun Ẹmi Mimọ gbọ, ẹni ti n sọ mi di mimọ ati gbogbo
ayanfẹ eniyan Ọlọrun.
Ibere: Iwọ wi pé awọn baba rẹ nipa ti Ọlọrun ati awọn iya rẹ nipa ti
Ọlọrun se ileri fun ọ pe, iwo o pa ofin Ọlọrun mọ. Wi fun mi melo ni mbẹ?
Idahun: Mẹwa.
Ibere: Ewo ni wọn?
Idahun: Ọkan naa ti Ọlọrun so ni ori ogun ti Eksodu pe, Emi ni Olúwa Ọlọrun rẹ
ti o mu ọ jade kuro ni ilẹ Egipti, lati oko ẹru jade wa.
I. Iwọ ko gbọdọ ni Ọlọrun miran pẹlu mi
II. Iwọ ko gbọdọ ya erekere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke mbẹ,
tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ; tabi ti inu omi ti mbẹ nisalẹ ilẹ; Iwọ ko
gbọdọ tẹriba fun won, bẹni iwọ ko gbọdọ sin wọn; nitori emi ni Olúwa Ọlọrun rẹ.
Ọlọrun owu ni mi, ti mbẹ ẹsẹ awọn baba wo lara ọmọ, titi de iran kẹta ati ẹkẹrin
ninu awọn ti o korira mi, emi a si ma fi anu han fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ mi, ti
wọn si n pa ofin mi mọ.
III. Iwọ ko gbọdọ pe orukọ Olúwa Ọlọrun rẹ lasan: nitori Olúwa ki yoo ka awọn ti n
pe orukọ rẹ lasan si alailẹbi.
IV. Ranti ọjọ isinmi lati lo o ni mimọ. Ọjọ mẹfa ni iwọ o sisẹ, ti iwọ o si se isẹ
gbogbo: Sugbọn ọjọ keje ni ọjọ isinmi Olúwa Ọlọrun rẹ. Ninu rẹ, iwọ ko gbọdọ se
isẹkisẹ kan, iwọ, tabi ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin,
tabi ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, tabi ohun ọsin rẹ, tabi alajo rẹ ti mbẹ ninu odi rẹ.
Nitori ni ọjọ mẹfa li Olúwa da mbẹ oun ayé, okun ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn, o
si sinmi ni ọjọ keje; nitori naa ni Olúwa se busi ọjọ keje, o si ya a si mimọ.
V. Bọwọ fun baba oun iya rẹ: ki ọjọ rẹ ki o le pe ni ile, ti Olúwa Ọlọrun re
fifun o.
VI. Iwọ ko gbọdọ paniyan.
VII. Iwọ ko gbọdọ se pansaga.
VIII. Iwọ ko gbọdọ jale
IX. Iwọ ko gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ.
X. Iwọ ko gbọdọ sojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ ko gbọdọ sojukokoro si aya
ẹnikeji rẹ, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, tabi si ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, tabi si malu
rẹ, tabi si ketekete rẹ, tabi si ohun kohun ti ise ti ẹnikeji rẹ.
Ibere: Kini iwọ kọ ni olori nipa ofin wọnyii?
Idahun: Mo kọ nkan meji, ise mi si Ọlọrun, ati ise mi si ẹnikeji mi.
Ibere: Kini ise rẹ si Ọlọrun?
Idahun: Ise mi si Ọlọrun ni, lati ma gba a gbọ, lati ma bẹru rẹ ati lati ma fi
gbogbo aya, gbogbo iye, gbogbo ọkan, ati gbogbo agbara mi fẹ Ẹ, lati ma bọ Ọ, lati
ma dupẹ fun Un, lati ma pa orukọ rẹ, ati lati ma bọwọ fun orukọ mimọ rẹ, ati ọrọ
rẹ, ati lati ma sin in lododo ni ọjọ ayé mi gbogbo.
Ibere: Kini ise rẹ si ẹnikeji rẹ?
Idahun: Ise mi si ẹnikeji mi ni, lati ma fẹ ẹ bi emi tikara mi, ati lati ma se
si gbogbo eniyan bi mo ti n fẹ ki wọn ki o se si mi. Lati ma fẹ baba ati iya mi,
lati ma bu ọla fun wọn, ati lati ma ran wọn lọwọ; lati bu ọla fun Ọba, ati gbogbo
awọn ti a fi si abẹ oye rẹ, ati lati ma gbọ tiwọn; lati ma tẹriba fun gbogbo awọn
alakoso mi, awọn olukọ mi, awọn onsẹ Ọlọrun ati awọn olori mi; Lati ma rẹ ara mi
sile, lati ma bọwọ fun gbogbo awọn ti o san ju mi lọ; Ki n ma ti ipa ọrọ tabi ise
mi pa ẹnikẹni lara: Lati ma se ootọ ati ododo ni gbogbo ise mi: Ki n ma ni arankan
tabi irira ni ọkan mi; Lati ma pa ọwọ mi mọ kuro ni hihe ati ni jijale, ati ahọn mi
kuro ni sisọ ọrọ 'bi eke, ati sisata: lati ma wa ni titẹnu, airekọja, ati aileri;
Ki n ma sojukokoro, tabi ki n ma fẹ ini ẹlomiiran; sugbọn ki n kọ lati ma sisẹ
lododo, lati ni ini mi, ati lati ma sisẹ mi ni iru ipo ti yoo wu Ọlọrun lati pe mi
si.
Ibere: Ọmọ mi, mo eyi pe, iwọ ko le se nkan wọnyii fun ara rẹ, bẹni iwọ ko le
rin ninu ofin Ọlọrun, ki iwọ ki o si ma sin ni aisi akanse ore-ọfẹ rẹ, ti iwọ ni
iko lati ma tọrọ, ninu adura nigba gbogbo: njẹ, jẹ ki n gbọ bi iwọ ba le ka adura
Olúwa?
Idahun: Baba wa ti mbẹ ni mbẹ. Ki a bọwọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ
tirẹ ni ki a se ni ayé, bi wọn ti n se ni ọrun. Fun wa ni Ounjẹ oojọ wa loni. Dari
ẹsẹ wa ji wa, bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwọ; sugbọn
gba wa lọwọ bilisi. Amin.

Nigba naa ni Alufa yoo bere lọwọ ẹni ti (awọn ẹni ti) a o baptist pe:-

Iwọ ha ko esu ati gbogbo ise rẹ silẹ, afẹ asan ati ogo ayé, pẹlu ojukokoro
ifẹ gbogbo, ati ifẹkufẹ ti ise ti ara; tobẹ ti iwọ ki yoo ma tọ wọn lẹhin, bẹni
wọn ki yoo ma se amọna rẹ?
Idahun: Mo kọ gbogbo wọn silẹ.
Alufa: Iwọ gba Ọlọrun Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda ọrun oun ayé? Iwọ gba
Jesu Kristi gbọ, Ọmọ bibi Rẹ nikansoso Olúwa wa? Ati pe nipa Ẹmi Mimọ ni a ti
loyun Rẹ; a bi i ninu Maria Wundia; o jiya lọwọ Pontiu Pilatu, a kan a mọ agbelebu,
O ku, a si sin in; o sọkalẹ re ipo oku, ati pẹlu pe ni ọjọ kẹta o tun jinde, o re
oke ọrun, o si joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba Olodumare: ati pe nibẹ ni yoo tun pada
wa ni opin ayé, lati se idajọ ààyè oun oku?
Iwọ si gba Ẹmi Mimọ gbọ: Ijọ mimọ Eniyan Ọlọrun; Idapọ awọn, Eniyan Mimọ;
Idariji ẹsẹ; Ajinde ara ni isa oku; ati iye ti ko nipẹkun lẹhin iku?
Idahun: Gbogbo eyi ni mo gbagbọ tọkantọkan.
Alufa: Iwọ ha fẹ ki a baptisi rẹ ninu igbagbọ yi?
Idahun: Ifẹ inu mi ni.
Alufa: Iwọ ha n fẹ tọkantọkan lati gba Kristi Olúwa bi Olùgbàlà rẹ, ki o
si gbẹkẹle Oun nikansoso fun igbala layé yii ati layé ti mbọ?
Idahun: Ifẹ inu mi ni.
Alufa: Iwọ o ha ma fi igbagbọ pa ifẹ ati ofin mimọ Ọlọrun mọ, ki iwọ ki
o si ma rin ninu wọn ni ọjọ ayé rẹ gbogbo?
Idahun: Emi o pa a mọ nipa iranlọwọ Ọlọrun.

Ẹ jẹ ki a gbadura.

Ẹ sọ eleyi ni orukọ

N. Mo baptisi rẹ ni Orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ . (Amin).

Nigba naa ni Olori Ijọ o wi pé

AWA gba eleyi sinu agbo Ijọ Kristi, awa si saa ni ami Agbelebu, apẹrẹ pe
lẹhin eyi ki yoo tiju ati jẹwọ igbagbọ Kristi ti a kan mọ agbelebu, ati lati ba
ẹsẹ, ayé, ati esu ja bi ọkunrin labẹ ọpagun rẹ; ati lati duro bi ọmọ-ogun Kristi
nitotọ ati bi ọmọ-ọdọ rẹ titi opin ẹmi rẹ. Amin.
IDAPO MIMỌ

A ki yoo gba ẹnikẹni si Idapọ Mimọ ni Ijọ tabi Ẹkun ti ki ise inu ẹni ti eyi
ti o wa, laijẹ pe o ko fi iwe Alagba Ijọ tabi Ẹkun rẹ fi ọwọ si han, ti o si fihan
pe ẹni kikun ninu Ijọ oun.

Bi ẹnikẹni ninu awọn ti o ba fẹ wa si Idapọ Mimọ ba jẹ ẹni ti o han gbangba


pe igbesi ayé rẹ ko dara, tabi o ti ipa ọrọ tabi ise sẹ ẹnikeji rẹ, (eyi ti o le mu
itiju ati ẹgan ba Ijọ) bi Alagba ba mọ, yoo sọ fun un, ki o mase wa si Tabili
Olúwa, titi yoo fi fihan gbangba pe oun ronupiwada oun si se atunhu iwa; tabi pe
oun se atunse ọrọ tabi iwe ibi ti oun fi se ẹnikeji rẹ. Bẹẹ pẹlu ni Alufa ki yoo
gba awọn ti o ba mọ pe wọn mbẹ ninu odi yiyan ati irira si ara wọn si Idapọ Mimọ,
titi yoo fi mọ pe wọn ti pari ija. Bi ọkan ninu wọn ba fẹ pari ija, ti ekeji ko ba
fẹ, nigba naa Alufa yẹ ki o gba eyi ti o fẹ pari ija.

Nigba ti Idapọ Mimọ yoo ba tele Adura Owurọ lẹsẹ kan naa, Alagba le bẹrẹ Isin
Idapọ Mimọ lehin Ohun ti o tẹle Ẹkọ Kika Keji ninu Adura Owurọ.

Baba wa ti mbẹ ni mbẹ, Ki a bowo fun oruko rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni
ki a se ni ayé. Bi wọn ti n se ni mbẹ. Fun wa ni Ounjẹ oojọ wa loni. Dari ẹsẹ wa
ji wa. Bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwo: sugbọn gba wa
lọwọ bilisi. Amin.

ADURA

ỌLỌRUN Olodumare, ẹni ti gbogbo ọkan wa sipaya fun, ẹni ti gbogbo ifẹ inu wa
di mimọ fun, ati ẹni ti ohun ikọkọ kan ko fi ara pamọ lọdọ rẹ; Fi imisi Ẹmi Mimọ
rẹ we iro inu wa nu, ki awa ki o le ma fe o ni afẹtan, ki a si le ma gbe Orukọ mimọ
rẹ ga bi o ti yẹ; nitori Kristi Olúwa wa. Amin.

A o ka Ofin Mẹwa wọnyii ni Isin Idapọ Mimọ ni Ọjọ Isinmi. Sugbọn bi Isin
Idapọ Mimọ ba ju ekan lo ni Ọjọ Isinmi, a o fi awọn ọrọ Olúwa wa wọnyii dipo wọn.

Alagba: Jesu Kristi Olúwa wa wi pé, Gbo Israeli, Olúwa Ọlọrun wa, Olúwa kan ni.
Ki iwọ ki o fi gbogbo aya rẹ, ati gbogbo ọkan rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ Ọlọrun
Olúwa rẹ. Eyi ni ekini ati ofin nla. Ekeji si dabi rẹ, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara
rẹ. Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati woli rọ mọ.
Idahun: Olúwa, saanu fun wa, ki o si gbogbo ofin rẹ wọnyii si wa ni ọkan, awa mbẹbẹ
lọdọ rẹ.

OFIN MẸWA

Alagba: Ọlọrun sọ gbogbo ọrọ wọnyii pe; Emi ni Olúwa Ọlọrun rẹ: Iwọ ko gbọdọ ni
Ọlọrun miran pẹlu mi.
Idahun: Olúwa, sàánú fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ ya erekere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ ni oke
ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ile, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni
isalẹ ilẹ. Iwọ ko gbọdọ tẹriba fun wọn, bẹni iwọ ko gbọdọ sin wọn; nitori Emi ni
Olúwa, Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owu ni ni, ti mbẹ ẹsẹ awọn baba wo lara awọn ọmọ, titi de
iran ẹkẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi, Emi a si ma fi anu han ẹgbẹgbẹrun
awọn ti o fẹ mi, ti wọn si n pa ofin mi mọ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ pe orukọ Olúwa Ọlọrun rẹ lasan: nitori Olúwa ki yoo salai
debi fun awọn ti n pe oruko rẹ layé.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba : Ranti ọjọ Isinmi lati lo o ni mimọ. Ọjọ mẹfa ni iwọ o sisẹ, ti iwọ o
si se isẹ rẹ gbogbo; sugbọn ọjọ keje ni ọjọ Isinmi Olúwa Ọlọrun rẹ. Ninu rẹ iwọ ko
gbọdọ se isẹkisẹ kan, iwọ, tabi ọmọ rẹ okunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi ọmọ-ọdọ
rẹ okunrin, tabi ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, tabi ohun ọsin rẹ, tabi alejo rẹ ti mbẹ ninu
odi rẹ. Nitori ni ọjọ mẹfa ni Olúwa da mbẹ oun ayé, okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ
ninu wọn, o si sinmi ni ọjọ keje: nitori naa ni Olúwa se busi ọjọ keje, o si ya a
si mimọ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Bọwọ fun baba oun iya rẹ: ki ọjọ rẹ ki o le pẹ ni ile ti Olúwa Ọlọrun
rẹ fifun ọ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ paniyan.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ se pansaga
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ jale
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ jẹri eke si ẹnikeji rẹ.
Idahun: Olúwa, saanu fun wa, ki o si tẹ ọkan wa si ati pa ofin yi mọ.
Alagba: Iwọ ko gbọdọ sojukokoro si ile ẹnikeji rẹ, iwọ ko gbọdọ sojukokoro si
aya ẹnikeji rẹ, tabi ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ-odo rẹ obinrin, tabi malu rẹ,
tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ, tabi si ohunkohun ti ise ti ẹnikeji rẹ.
Idahun: Olúwa, sàánu fun wa, ki o si kọ gbogbo ofin rẹ wọnyii si wa ni ọkan, awa
mbẹbẹ lọdọ rẹ.

Nigba naa ni Alagba o gba ọkan ninu awọn Adura meji yi fun Ọba, yoo si wi pé:

Ẹ JẸ KI A GBADURA

ỌLỌRUN Olodumare, ijọba ẹni ti ko nipẹkun, ati agbara ẹni ti ko ni opin;


Sàánu fun gbogbo Ijọ rẹ; ki iwọ ki o si se akoso ọkan N- Ọba (Baalẹ) Iransẹ ayanfẹ
rẹ, (bi oun ti mo iransẹ ẹni ti oun ise) ki o le ma tọju ọla ati ogo rẹ ju ohun
gbogbo lọ: ati ki awa ati gbogbo awọn eniyan rẹ (bi a si ti n ro bi o ti yẹ, ọla
ẹni ti o ni,) ki a ma fi otitọ sin in, ki a ma bu ọla fun un, ki a si ma fi iparamọ
gba tirẹ gbọ, nipa tirẹ, ati nitori tirẹ, gẹgẹ bi ọrọ ati ilana rẹ ti o ni ibukun;
nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni ti o wa ti o si n jọba pẹlu iwọ ati Ẹmi Mimọ , lai
Ọlọrun kan, ayé ainipẹkun. Amin.

Tabi eyi,

OLODUMARE ati ayérayé Ọlọrun, ninu ọrọ mimọ rẹ ni a gbe kọ wa pe, ọkan awọn
Ọba mbẹ ni ikawọ ati akoso rẹ, pe Iwọ ni idari wọn ti o si ma itọ wọn nipa ọgbọn rẹ
gẹgẹ bi o ti yẹ; Awa n fi iparamọ bẹbẹ lọdọ rẹ lati dari ati lati se akoso ọkan
N- Ọba (Baalẹ,) Iransẹ rẹ, ni iro, ọrọ, ati ise rẹ gbogbo, ki o le ma tọju ọla ati
ogo rẹ, ki o si le ma humọ ati pa awọn eniyan rẹ mo ti a fi si isọ rẹ ni irọra,
alafia, ati ni iwa-bi-Ọlọrun: Fi eyi funni, Baba alaanu, nitori ti ọmọ rẹ ọwọn,
Jesu Kristi Olúwa wa. Amin
Nigba naa ni Alagba o gba Adura ti a yan fun ọjọ na.

Mo gba Ọlọrun kan Baba Olodumare gbọ, Ẹlẹda mbẹ oun ayé. Ati ohun gbogbo ti a
n ri ati eyi ti a ko ri.

Mo gba Olúwa kan Jesu Kristi gbọ, ọmọ bibi nikansoso ti Ọlọrun, Ti a bi lati
ọdọ Baba rẹ saaju ayé gbogbo, Ọlọrun lati inu Ọlọrun, Imọlẹ lati inu Imọlẹ, Ọlọrun
tikararẹ lati inu Ọlọrun tikararẹ, ẹni ti a bi ti a ko da, ti ise ara kan naa pẹlu
Baba; Lati ọwọ ẹni ti a ti da ohun gbogbo, Ẹni, nitori awa eniyan, ati nitori
igbala wa, ti o ti mbẹ wa si ile, ẹni ti o si mu awo ara nipa Ẹmi Mimọ lara Maria
Wundia. O si di eniyan, A si kan a mọ agbelebu pẹlu nitori wa lọwọ Pontiu Pilatu. O
jiya a si sin in, Ni ọjọ keta o si tun jinde gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun, O si lọ soke mbẹ,
O si joko lọwọ ọtun Baba. Yoo si tun pada wa ti oun ti ogo, lati se idajọ aye ati
oku; Ijọba ẹni ti ki yoo nipẹkun.

Mo si gba Ẹmi Mimọ gbọ, Olúwa ati Olufunni ni iye, ẹni ti n ti ọdọ Baba ati
Ọmọ wa, Pẹlu Baba ati Ọmọ ẹni ti a n sin ti a sin yin logo pọ, ẹni ti o ti ẹnu awọn
Woli sọrọ. Mo si gba Ijọ Katoliki kan ati awọn Aposteli gbọ, Mo jẹwọ Baptismu kan
fun imukuro ẹsẹ, Emi si n reti ajinde oku, Ati iye ayé ti mbọ wa. Amin.

Nigba naa ni a o bẹrẹ si gba ọrẹ Ijọ, Alagba yoo si ma ka ninu awọn ọrọ
Ọlọrun wọnyii. Nigba ti a ba gba ọrẹ tan, a o fi tọwọ-tọwọ gbe e tọ Alagba wa, ẹni
ti yoo gba adura yi, ti yoo si fi irẹlẹ gbe ọrẹ naa sori Tabili Mimọ.

ADURA

OLÚWA, masai gba ọrẹ awọn eniyan rẹ wọnyii, ki o si lo wọn fun ogo rẹ. dari
gbogbo aipe tabi abuku wa ji wa, ki o si fi ibukun rẹ fun awọn ti o mu awọn ọrẹ
atinuwa wọnyii wa fun ọ; nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.

Ẹ JẸ ki imọlẹ yin ki o mọlẹ to bẹ niwaju eniyan, ki wọn ki o le ma ri isẹ


rere yin, ki wọn ki o si le ma yin Baba yin ti mbẹ ni mbẹ logo. Mat. 6: 19- 20
Ohunkohun ti ẹyin n fẹ ki eniyan ki o se si yin, bẹẹni ki ẹyin ki o se si wọn
gẹgẹ; nitori eyi ni ofin ati awọn woli. - Mat. 7: 12.
Kii ise gbogbo ẹni ti n pe mi ni Olúwa, Olúwa, ni yoo wọle ijọba mbẹ, bikose
ẹni ti n se ifẹ Baba mi ti mbẹ ni mbẹ. Mat. 7: 21
Sakeu dide duro, o si wi fun Olúwa pe; Sa wo, Olúwa, aabọ ohun ini mi ni mo
fi tọrẹ fun awọn olupọnju; bi mo ba si fi ẹsun eke gba ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo
san an pada ni ni ilọpo mẹrin. Luku 19: 8.
Tani ilọ si ogun nigba kan ri ni inawo ara rẹ? tabi igbin agbala ajara, ti
ki si ijẹ ninu eso rẹ? Tabi tani ibọ ọwọ ẹran, ti ki ijẹ ninu wara ọwọ ẹran na? I
Kor. 9: 7
Bi awa ba ti funrugbin ohun ti emi fun yin, ohun nla ha ni bi awa o ba si ka
ohun yin ti ise ti ara? I Kor. 9: 11.
Ẹyin ko mọ pe, awọn ti n se iransẹ ohun mimọ ninu ohun ibi mimọ ni wọn nje?
ati awọn ti n duro ti pẹpẹ, pẹpẹ ni wọn mba se ajọpin? Gẹgẹ bẹẹ ni Olúwa si ti
lana silẹ, pe awọn ti n waasu Ihinrere, ohun Ihinrere ni ki wọn ma jẹ. I Kor. 9:
12, 14.
Ẹni ti o ba funrugbin kiun, kiun ni yoo ka; ẹni ti o ba si funrugbin pupọ,
pupọ ni yoo ka. Jẹ ki olukuluku se gẹgẹ bi o ti pinnu ni ọkan rẹ, ki ise pẹlu
kikun, tabi ti aigbodo mase; nitori Ọlọrun fẹ oninudidun olore. 2 Kor. 9: 6, 7
Ki ẹni ti a n ko ninu ọrọ na ki o pese fun ẹni ti nkoni ninu ohun rere
gbogbo. Ki a mase tan yin je, a ko le gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan ba
funrugbin oun ni yoo ka pẹlu. Gal. 6: 6, 7
Njẹ bi awa ti ni akoko, jẹ ki a sore fun gbogbo eniyan, ati pẹlu-pẹlu fun
awọn arale igbagbọ. Gal. 6: 10
Sugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itelorun ere nla ni: nitori awa ko mu ohun kan wa
si ayé, o si daniloju pe awa ki yoo si le mu ohun kan ti inu rẹ jade. I Tim. 6: 6,
7.
Kilo fun awọn ti o lọrọ ni ayé yi, kin wọn ki o mura lati ma se itore, ki inu
wọn ki o si ma dun lati pin fun’ni; ki wọn ki o ma ko ipilẹ rere jo fun ara wọn de
igba ti mbọ, ki wọn ki o le de ibi iye ti ko nipekun. I Tim. 6: 17, 19.
Ọlọrun ki ise alaisododo, ti yoo fi gbagbe ise ati lala ife yin, ti ẹyin ti
fihan sipa Orukọ rẹ, niti ẹyin ti n se iransẹ fun awọn eniyan mimọ, ti ẹ si n se e
sibẹ. Heb. 6: 10
Ati ma sore, oun ati ma pin fun’ni, e mase gbagbe: nitori pe iru ẹbọ rẹ ni
inu Ọlọrun dun si jojo. Heb. 6: 16
Ẹnikẹni ti o ba ni ohun rere ayé yi, ti o si ri arakunrin rẹ ti ise alaini,
ti o si se ilẹkun iyọnu rẹ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti mba Olúwarẹ gbe? I John. 3:
17
Fi tore ninu ohun inu rẹ, ma si se yiju rẹ kuro lara talaka kan; nje Olúwa ki
yoo si yiju kuro lara rẹ. Tobit. 4.
Ma saanu gẹgẹ bi agbara rẹ. Bi iwọ ba ni pupọ, fi pupọ tọrẹ: bi iwọ ba ni
die, si roju fi tọrẹ ninu diẹ na pẹlu inu didun: ni sise be iwọ nko ebun rere jo
fun ara rẹ de ojo oni. Tobit 4.
Ẹni ti o ba saanu fun olupọnju Olúwa ni o win: ati ohun ti o fi fun’ni, yoo
san an pada fun uu. Owe. 19: 17.
Ibukun ni fun ẹni ti n pese fun olokunrun ati fun alaini: Olúwa yoo gba a
nigba ipọnju. Psa. 41: 1

Ẹ JẸ KI A GBADURA FUN GBOGBO IJỌ KRISTI NI AYÉ YI

OLODUMARE ati lai Ọlọrun Alaye, ẹni ti o ti ọwọ Aposteli rẹ mimọ ko wa lati
ma gbadura, lati ma bẹbẹ, ati lati ma dupẹ fun gbogbo eniyan; Awa n fi iparamọ bebe
lowo rẹ, ninu anu rẹ nla, ki iwọ ki o (gba ore anu ati ẹbun wa, ati ki o si) gba
adura wa wọnyii, ti awa n gba si Ọla-nla Iwa mimọ rẹ; awa mbẹbẹ lodo rẹ, ki iwọ ki
o ma mi ẹmi otitọ, isọkan, ati irepo, nigba gbogbo si gbogbo Ijọ mimọ rẹ: Ki iwọ
ki o si fi fun’ni, ki gbogbo awọn ti o jẹwọ Orukọ mimọ rẹ le ni ohun kan niti otitọ
ọrọ mimọ rẹ, ki wọn ki o si wa ni isọkan, ati ni ifẹ-bi-Ọlọrun. Awa si mbẹbẹ lọdọ
Rẹ lati to gbogbo orilẹ-ede ni ọna ododo ati alafia: ati lati dari gbogbo awọn Ọba
ati awọn Ijoye pe ki a le fi iwa-bi-Ọlọrun ati iwa pẹlẹ se akoso awọn eniyan Rẹ
labẹ oye wọn; ki o si fifun Ọba, awọn Igbimọ rẹ, ati gbogbo awọn ti a fi si ibi ọla
labẹ rẹ, ki wọn ki o le ma fi otitọ, aisoju saaju dajọ aisegbe, lati se iwa-buburu
ati iwa-ẹsẹ nise, ati lati gbe isin otitọ rẹ ati iwa rere leke. Baba mbẹ, fi ore-
ọfẹ fun gbogbo awọn Bisopu, ati Alagba, ki wọn ki o le ma fi iwa ati ẹkọ wọn gbe
ọrọ rẹ otitọ ti o ni iye kalẹ, ki wọn ki o si le ma se ise ipin-funni awọn
Sakramẹnti rẹ mimọ, bi o ti tọ ati bi o ti yẹ: Ki o si fi ore-ọfẹ rẹ mbẹ fun gbogbo
eniyan rẹ; ati pẹlupẹlu fun ọjọ yi ti o wa nihin nisinsin yii; pẹlu ọkan tutu ati
ọwọ ti o yẹ ki wọn ki o ma gbọ, ki wọn ki o si ma gba ọrọ mimọ rẹ; ki wọn ki o ma
sin o nitotọ ni mimọ iwa ati ni ododo ni ọjọ ayé wọn gbogbo. Awa si n fi iparamọ
bebe lodo rẹ ninu ore rẹ, Olúwa, lati rẹ on ati ran gbogbo wọn lowo ni ayé ti n
koja yi, awọn ẹni ti o wa ninu ise, ni ibinujẹ, ni aini, ninu aisan, tabi ninu
ipọnju miran. Awa si n fi ibukun fun Orukọ mimọ rẹ pẹlu, nitori gbogbo awọn
eniyan rẹ ti o ti fi ayé yi sile ni igbagbọ ati ni iberu rẹ; awa mbebe lodo rẹ, ki
iwọ ki o fi ore-ọfẹ fun wa bẹẹ, lati ma tọpa iwa rere wọn, ati pẹlu wọn ki awa ki o
le se alabapin ijọba ọrun rẹ: Baba, fi eyi funni, nitori Jesu Kristi Onilaja ati
Alagbawi wa nikansoso. Amin.
Bi oore anu tabi ẹbun ko ba si, a o fo ọrọ wọnyii, (gba ore anu ati ẹbun wa)
ni aika wọn.
ỌRỌ IYANJU
OLUFẸ ọwọn, ni ọjọ- oni, emi n gbero, nipa iranlọwọ Ọlọrun, lati se ipinfunni
Sakramenti Ara oun Ẹjẹ Kristi ti o ni itunu julọ, fun gbogbo awọn ẹni ti ọkan wọn
ba fa si i ni ifọkansin Ọlọrun; lati gba a ni iranti Agbelebu ati Iya-rẹ ti o toye;
nipa eyi kan naa ti awa n ri imukuro ẹsẹ wa gba, ti a si n mu wa di alabapin ijọba
mbẹ. Nje nitori naa ise wa ni lati fi iparamọ ati tọkantọkan dupẹ bi o ti to julọ
lọwọ Ọlọrun Olodumare Baba wa ti mbẹ ni ọrun, nitori ti o fi Jesu Kristi ọmọ rẹ
Olùgbàlà wa funni, ki ise kiki lati ku fun wa, sugbọn pẹlu lati ma se Ounjẹ ati
ohun ibo-ni ti emi ni Sakramenti mimọ naa. Bi o ti jẹ ohun mimọ ati ohun itunu fun
awọn ti o gba a bi o ti yẹ, ti o si se ohun ewu fun awọn ti o laya lati gba a layé;
ise mi ni lati gba yin niyanju niwoyi, lati ro bi ohun ijinle mimọ naa ti tobi to,
ati ewu nla ti aigba a bi o ti yẹ; bẹni ki eyi ni ki o si wa ọkan yin jalẹ koro,
(ki ima se ni awa afowota, bi awọn ẹlẹtan niwaju Ọlọrun; sugbọn be) ki ẹyin ki o le
wa ni mimọ ati ni aileri si iru Ase mbẹ yi, ninu asọ-iyawo ti Ọlọrun n fẹ ninu ọrọ
mimọ rẹ, ki a si le gba yin ni alabapin ti o yẹ ti Tabili mimọ naa.
Ọna ati ipa lati wa sibẹ niyi; Ikini, ki ẹyin ki o fi ilana ofin Ọlọrun wadi
iwa ati ise yin; ninu ohunkohun ti ẹyin ba si woye pe, ẹyin ti se, iba se ni ifẹ,
ni ọrọ ẹnu, tabi ni ise, ninu rẹ ni ki ẹyin ki o pohunrere ẹkun ẹsẹ yin, ki ẹyin ki
o si jẹwọ rẹ fun Ọlọrun Olodumare, ki ẹ si pinnu lati tun iwa yin se. Bi ẹyin ba
si woye pe ẹsẹ yin ki ise kiki si Ọlọrun nikan, sugbọn si ẹnikeji yin pẹlu; njẹ ki
ẹyin ki o ba wọn laja; ki ẹyin ki o si mura ati san ẹsan pada fun wọn, ati lati tu
wọn ninu gẹgẹ bi o ti wa ni ipa yin, nitori ibi, ati iwosi ti ẹ se wọn; ki ẹyin ki
o si ma mura bẹẹ gẹgẹ lati dariji awọn ẹlomi ti wọn si ti se yin, bi ẹyin ti n fẹ
idariji ẹsẹ yin lowo Ọlọrun: nitori bi e ko ba se be, gbigba Idapọ mimọ na yoo wulẹ
mu ẹbi yin di pupọ. Nitori naa bi enikan ninu yin ban se asọrọ-odi si Ọlọrun,
adena, tabi ase-bajẹ ọrọ rẹ, agbere, tabi alarankan, tabi onilara, tabi ẹni ti o wa
ninu ẹsẹ, buburu miran, e ronupiwada ẹsẹ yin, bikose be, mase wa si ibi Tabili mimọ
na; nitori lẹhin igba ti o ba ti gba Sakramẹnti mimọ naa tan, ki esu mase ma ba wo
inu rẹ, bi o ti wo inu Judasi, ki o si fi ẹsẹ gbogbo kun inu rẹ, ki o si mu ati ara
ati ọkan rẹ lo si inu iparun.
Ati nitori bi ko ti yẹ, ki ẹnikẹni ki o wa si Idapọ mimọ naa laigbẹkẹle anu
Ọlọrun patapata, ati laini ibajẹ ọkan: nitori naa bi ẹnikẹni ninu yin ko ba ni
ibalẹ ọkan lẹhin ọrọ wọnyii, sugbọn ti n fẹ itunu ati imọran si i, ki o to mi wa,
tabi ki o to Iransẹ Ọlọrun miran lo ti o moye ti o si gbọn, ki o le ri anfani
ifiji ẹsẹ, pẹlu imọran ati ẹkọ niti ohun ẹmi, lati mu ọkan rẹ balẹ, ati lati mu
gbogbo onnu ati iyemeji kuro.

TABI ỌRỌ IYANJU YII


ARA olufẹ ọwọn, ni ọjọ- oni, emi n gbero, nipa ore-ọfẹ Ọlọrun lati se
ipinfunni Ounjẹ Alẹ Olúwa; ni Orukọ Ọlọrun ni emi n pe gbogbo ẹyin ti o wa nihin
yIi, ki e wa sibẹ; mo si bẹ yin, nitori Jesu Kristi Olúwa, ki ẹyin ki o mase kọ
lati wa, bi Ọlọrun tikararẹ ti n fi ifẹ rẹ pe yin. Ẹyin mọ bi o ti se ohun ibinujẹ
ati abuku to, nigba ti eniyan kan ba se ase pupọ, ti o fi oniruru Ounjẹ se tabili
rẹ ni ọsọ, ti ko si ohun ti o ku, bikose ki awọn ti a pe ki o joko, sugbọn ki awọn
ti a pe se alaimore tobẹ, ki wọn si ko, lainidi, lati wa. Tani ninu yin ti inu rẹ
ki yoo ru? Tani ki yoo ro pe abuku ati iwọsi nla ni a se si oun? Njẹ nitori naa,
ẹyin olufẹ ọwọn julọ nipa ti Kristi; ẹ ma kiyesi ara yin gidigidi bi ẹ ti n fasẹhin
kuro nibi Ounjẹ-alẹ mimọ yii, ki ẹyin ki o ma ba ru ibinu Ọlọrun si ara yin. Ko
sọrọ fun ẹnikan lati wi pe, Emi ki yo jẹ Ounjẹ-alẹ, nitori ise ayé di mi lọwọ
sugbọn iru awawi wọnni ko le kọja, ko si le se itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. Bi ẹnikan ba
si wi pé, ẹlẹsẹ buburu ni emi, nitori naa ni mo se bẹru lati wa: ehase ti ẹyin ko
ronupiwada, ki ẹ si tun iwa yin se? Nigba ti ẹyin o ba pada tọ Ọlọrun lọ, ẹyin o
se awawi pe, ẹyin ko ti imura tan? Ẹ ba ara yin ro o gidigidi bi iru awawi wọnyii
yoo ti jẹ asan niwaju Ọlọrun. Awọn ti o kọ asẹ ninu Ihinrere, nitori ti wọn ra
ile, tabi nitori ti wọn n lo idan ajaga malu wo, tabi nitori ti wọn gbeyawo, a ko
gba awawi wọn, sugbọn a ka wọn ni alayé si asẹ ọrun.
Nipa temi, emi o mura; ati gẹgẹ bi ise Oye mi, mo pe yin lo Orukọ Ọlọrun, mo
pe yin ni Orukọ Kristi, emi n gba yin niyanju, bi ẹyin ba ti fẹ igbala ọkan ara
yin, ki ẹyin ki o se alabapin Idapọ mimọ yi. Ati bi ọmọ Ọlọrun ti rẹ ara rẹ silẹ
lati ku lori Agbelebu nitori igbala ọkan yin; bẹẹ ni o si jẹ isẹ yin lati gba Idapọ
na ni iranti ẹbọ iku rẹ, bi oun tikararẹ ti palasẹ: bi ẹyin ba si ko lati se e, e
ro o ninu ara yin bi abuku ti ẹyin n se si Ọlọrun ti tobi to, ati bi iya ti o
rodede sori yin tipo to; nigba ti ẹyin ba mọọmọ fasẹhin kuro nibi Tabili Olúwa, ti
ẹyin si ya ara yin kuro lọdọ awọn ara yin, ti o wa lati fi asẹ ọrun naa bọ ara wọn.
Bi ẹyin ba ro nkan wọnyii gidigidi, nipa ore-ọfẹ Ọlọrun ẹ o yi ọkan yin pada;
nitori lati ri eyi gba, awa ki yoo dẹkun lati ma fi iparamọ bẹbe lọdọ Ọlọrun
Olodumare Baba wa ti mbẹ ni ọrun.

ỌRỌ IYANJU NI IGBA SAKRAMẸNTI


OLUFẸ ọwọn nipa ti Olúwa, ẹyin ti n fe wa si Idapọ mimọ Ara oun Ẹjẹ Kristi
Olùgbàlà wa, ẹ ro bi Paulu ti gba gbogbo eniyan niyanju lati wadi ara wọn jalẹ
koro, ki wọn ki o to dagba lati wa jẹ akara naa, ati lati wa mu ninu Ago naa.
Nitori bi anfani rẹ ti pọ to, bi awa ba fi Irònúpiwàdà ọkan nitotọ ati ayi igbagbọ
gba Sakramẹnti mimọ naa; (nitori igba naa ni awa n je eran-ara Kristi, ti a si n mu
eje rẹ nipa ẹmi; nigba na ni awa n gbe inu Kristi, ti Kristi si n gbe inu wa; awa
di ọkan pẹlu Kristi, Kristi si di ọkan pẹlu wa;) bẹẹ ni ewu naa si tobi, bi awa ba
gba ẹyin ni alayé. Nitori igba naa ni awa jẹbi Ara oun Ẹjẹ Kristi Olùgbàlà wa; awa
n jẹ, awa si n mu ẹbi ara wa, ara ko ro Ara Olúwa; awa n tina bọ ibinu Ọlọrun si
ara wa lori; awa n tọ ọ lati fi oniruru arun ati iku ba wa ja. Nitori naa ara, ẹ da
ara yin ni ẹjo, ki a ma ti ọwọ Ọlọrun da yin ni ẹjọ; ẹ ronupiwada nitotọ nitori ẹsẹ
yin ti o ti kọja; ẹ ni igbagbọ aye ati igbagbọ ti o duro sinsin ninu Kristi
Olùgbàlà wa; ẹ se atunhu iwa, ki ẹyin ki o si wa ni ifeni afetan si gbogbo eniyan;
be ni ẹyin o si se alabapin ohun ijinle mimọ wọnyii bi o ti ye. Ati bori ohun
gbogbo ki ẹyin ki o ma fi iparamọ ati tọkantọkan dupẹ gidigidi lọwọ Ọlọrun, Baba,
Ọmọ, ati Ẹmi Mimọ , nitori idande arayé nipa iku ati iye Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti
ise Ọlọrun ati eniyan; ẹni ti o rẹ ara rẹ silẹ, titi o fi de iku ori Agbelebu, fun
awa otosi ẹlẹsẹ, awa ti o wa ni okunkun ati ninu ojiji iku; ki o le sọ wa di ọmọ
Ọlọrun, ati ki o le gbe wa soke si iye ti ko nipẹkun. Ati nitori ki awa ki o le ma
ranti nigba gbogbo ifẹ nla Olúwa wa, Jesu Kristi Olùgbàlà wa nikansoso, ti o ku
bayi fun wa, ati ore ainiye ti o fi ẹjẹ rẹ iyebiye ti o ta silẹ gba fun wa; o si
ti da, o si ti lana ohun ijinlẹ mimọ silẹ, bi igbọwọ ifẹ rẹ, ati fun iranti iku rẹ
titi lai, fun itunu nla wa ti ko ni opin. Nitori naa, Oun pẹlu Baba ati Ẹmi Mimọ
ni ki a ma fi ọpẹ fun titi lai bi o ti yẹ; ki a ma fi ara wa le ifẹ ati iwa mimọ rẹ
lọwọ patapata, ki awa ki o si ma gbiyanju lati sin in nitotọ ni mimọ-iwa ati ni
ododo ni ọjọ ayé wa gbogbo. Amin.

Nigba na ni Alagba o wi fun pe:

ẸYIN ti o ronupiwada ẹsẹ yin nitotọ ati tọkantọkan, ti ẹyin si wa ninu ifẹ
ati ifẹni si ẹnikeji yin, ti ẹyin si n fẹ lati ma rin ni iwa titun, lati ma tọpa
ofin Ọlọrun, ati lati ma rin lati isinsin yii lọ ni ọna mimọ rẹ. Ẹ fi igbagbọ sunmọ
ihin, ki ẹ si gba Sakramẹnti mimọ yi fun itunu yin; ki ẹ si fi iparamose ijẹwọ fun
Ọlọrun Olodumare, ki ẹ si fi ọkan tutu kunlẹ ni ekun yin.

IJẸWỌ
ỌLỌRUN Olodumare, Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Ẹlẹda ohun gbogbo, Onidajọ
gbogbo eniyan; Awa jẹwọ, awa si n pohunrere ẹkun ọpọlọpọ ẹsẹ ti awa ti n da, ati
iwa buburu wa. Ti awa ti n hu nigbakugba, ni ero, ni ọrọ, ati ni iwa hihu, si
Ọlanla iwa mimọ rẹ. Awa n tọ ibinu ati irunu rẹ ti o to julọ si ara wa. Tọkantọkan
ni awa ronupiwada, Awa si n kaanu isise wa wọnyi lati inu wa; Ẹdun ni iranti wọn da
fun wa; Ẹru wọn ko se igbe. Saanu fun wa, Saanu fun wa Baba alanu julọ; nitori Jesu
Kristi Ọmọ rẹ Olúwa wa, Dariji gbogbo eyi ti o ti kọja ji wa; Ki iwọ ki o si
fifunni lai lẹhin eyiyi, ki awa ki o le maa sin, ki a le ma wu ọ. Ni ọtun iwa, Fun
ọla oun ogo Orukọ rẹ; Nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.

IFIJI
ỌLỌRUN Olodumare, Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ẹni ti o ti inu anu rẹ nla se ileri
idariji ẹsẹ fun gbogbo awọn ti o tinu ronupiwada, ati ti wọn si fi igbagbọ otitọ
yipada si i: Ki o saanu fun yin: ki o dariji yin, ki o gba yin kuro ninu ẹsẹ yin
gbogbo; ki o mu ẹsẹ yin duro, ki o si mu yin ni ara le ninu ore gbogbo; ki o si mu
yin de inu iye ti ko nipẹkun; nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.

Nigba naa ni Alagba o wi pé:


Ẹ gbọ ọrọ itunu ti Kristi Olùgbàlà wa sọ fun gbogbo awọn ti o yipada si
nitotọ.
GBOGBO ẹni ti o ba n sisẹ, ti a si di ẹru wuwo le lori, ki o tọ mi wa, emi o
si fi isinmi fun yin. Mat. 11: 28
Ọlọrun fẹ arayé to bẹẹ gẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ nikansoso funni, pe, ẹnikẹni
ti o ba gba a gbọ ki yoo segbe, sugbọn yoo ni iye ti ko nipẹkun. Joh. 3: 16

Ẹ gbọ bi Paulu ti wi pe:


Eyi yi ni ọrọ otitọ, o si yẹ fun itẹwọgba gbogbo, pe Kristi Jesu wa si ayé
lati gba ẹlẹsẹ la. I Tim. 1: 15

Ẹ gbọ bi Johannu ti wi pẹlu:


Bi ẹnikẹni ba sẹ, awa ni Alagbawi kan lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo; oun si
ni etutu fun ẹsẹ wa. I Joh. 2: 1

Lẹhin eyi ni Alagba o wi pé:


Alagba: Ẹ gbe ọkan yin soke.
Idahun: Awa gbe wọn soke si Olúwa.
Alufa: Ẹ jẹ ki awa ki o dupẹ lọwọ Olúwa Ọlọrun wa.
Idahun: O yẹ, o si to lati ma se bẹẹ.

Nigba naa ni Alagba yoo yipada si Tabili Olúwa, yoo si wi pé:

O YẸ jọjọ, o tọ, isẹ isin wa si ni, nigba gbogbo, ati nibi gbogbo, ki awa ki
o ma dupẹ lọwọ rẹ, Olúwa, *Baba Mimọ, Olodumare, ayérayé Ọlọrun.
*Ọrọ wọnyii, Baba Mimọ, ni ki a fo ni ọjọ Ọlọrun Mẹtalọkan.

Nihin yii ni ki Alagba ki o gba adura naa ti a yan silẹ fun ọjọ ọtọ, tabi eyi.

NITORI NAA pẹlu awọn Angẹli ati awọn Olori Angẹli, ati pẹlu gbogbo awọn egbe
ọrun, awa yin, awa si n gbe Orukọ rẹ ti o ni ogo ga; awa si yin Ọ titi lai pe,
Mimọ, mimọ, mimọ, Olúwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ọrun oun ayé kun fun ogo rẹ: Ogo ni
fun Ọ.

ADURA FUN ỌJỌ OTO


Ni Ọjọ-Ibi Kristi ati ọjọ meje lẹhin rẹ
NITORI TI iwọ fi Jesu Kristi Ọmọ rẹ nikan soso funni lati di bibi ni aya oni
fun wa; nipa isẹ Ẹmi Mimọ , ẹni ti o di eniyan iyeniyan, ni ara Maria Wundia iya
rẹ; ati ni aini abawọn ẹsẹ, lati sọ wa di mimọ kuro ninu ẹsẹ gbogbo. Nitori naa
pẹlu awọn Angẹli, &c.

Ni Ọjọ Ajinde, ati ọjọ meje lẹhin rẹ.


SUGBỌN ju gbogbo rẹ lo, ise wa ni lati yin o nitori Ajinde ti o logo ti Ọmọ
rẹ Jesu Kristi Olúwa wa; nitori oun ni Ọdọ aguntan Irekọja toto, ti a fi rubọ fun
wa, ti o si ti ko ẹsẹ ayé lo; nipa iku rẹ ẹni ti o si ti pa iku run, ati nipa
ajinde rẹ si iye, ti o si ti tun mu iye ti ko nipẹkun pada wa fun wa. Nitori naa
pẹlu awọn Angẹli, &c.

Ni ọjọ Igoke-rẹ mbẹ, ati ọjọ meje lẹyin rẹ.


NITORI ọmọ rẹ olufẹ ọwọn julọ Jesu Kristi Olúwa wa; lẹhin Ajinde rẹ ti o ni
ogo julọ, ẹni ti o fi ara han fun gbogbo awọn Aposteli rẹ ni gbangba, ni oju wọn ti
o si lo soke ọrun lo ipese ipo fun wa, pe, nibi ti oun gbe wa, nibẹ ni awa o goke
lọ pẹlu, ti awa o si jọba pẹlu rẹ ninu ogo. Nitori naa pẹlu awọn Angẹli, &c.

Ni Ọjọ-isinmi Funfun, ati ọjọ mẹfa lẹhin rẹ


NITORI Jesu Kristi Olúwa wa; gẹgẹ bi ileri otitọ ẹni ti Ẹmi Mimọ ti mbẹ sọkalẹ wa
ni aya ọjọ oni ni ojiji pẹlu iro nla, bi ẹni pe efufu lile, ni aworan ahọn ina, ti
o si ba le awọn Aposteli, lati ko wọn, ati lati fi ẹsẹ wọn le ona otito gbogbo; o
fun wọn ni ebun oniruru ede, ati igboya pẹlu itara gbigbona, lati ma waasu ihinrere
fun gbogbo orilẹ-ede nigba gbogbo, nipa eyi ti a ti mu wa jade kuro ninu okunkun
ati isina sinu imọlẹ gbangba, ati sinu otito imọ rẹ ati ti Ọmọ rẹ, Jesu Kristi.
Nitori naa pẹlu awọn Angẹli, &c.

Ni Ọjọ-isinmi ti Mẹtalọkan.
ẸNI TI ise Ọlọrun kan, Olúwa kan; ki ise kiki Ẹnikansoso, sugbọn Ẹni-mẹta ni
Ohun iwa kan. Nitori eyi ti awa gbagbọ ni ti ogo Baba, oun naa ni awa gbagbọ ni ti
Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ pẹlu, laisi iyatọ tabi aidọgba. Nitori naa pẹlu awọn Angli,
&c.

Nigba naa ni Alagba yoo kunlẹ lẹba Tabili Olúwa, ni orukọ awọn ti yoo wa si Idapọ,
yoo si gba adura yii.
OLÚWA alaanu, awa ko dagba lati wa si Tabili rẹ yi, ni igbẹkẹle ododo ara
wa, bikose ni ọpọlọpọ anu rẹ nla. Awa ko yẹ to bẹẹ lati sa eerun akara labẹ Tabili
rẹ. Sugbọn iwọ ni Olúwa naa, iwa ẹni ti ise ati saanu nigbagbọ: Nitori naa, fifun
wa Olúwa olore-ọfẹ, lati jẹ ẹran-ara Jesu Kristi Ọmọ rẹ ọwọn, ati lati mu ẹjẹ rẹ
bẹẹ, ki ara rẹ ki o le sọ ara ẹsẹ wa di mimọ. Ati ki ẹjẹ rẹ iyebiye le wẹ ọkan wa
nu, ki awa ki o si le ma gbe inu rẹ titi lai, ki oun ki o si ma gbe inu wa. Amin.

Nigba ti Alagba ba duro niwaju Tabili, ti o si to Akara ati Waini lẹsẹẹsẹ tan, yoo
gba Adura Isọ-di-mimọ pe:
ỌLỌRUN Olodumare, Baba wa ti mbẹ ni ọrun, ẹni ti o ti inu iyọnu anu rẹ fi
Jesu Kristi ọmọ rẹ nikansoso funni lati jiya iku lori agbelebu fun idande wa; (nipa
ẹbọ kan ti o fi ara rẹ ru lẹkan soso) ẹni ti o ru ẹbọ itẹnilọrun, ẹbọ arukun, ati
aruda, ẹbọ ti o tọ, fun ẹsẹ gbogbo ayé; o si da a silẹ, ati ninu Ihin-rere rẹ mimọ,
o fi ohun silẹ fun wa lati ma se e titi, ni iranti iku rẹ iyebiye, titi yoo si fi
fun pada wa; Gbọ tiwa, Baba alanu julọ, gidigidi ni awa n fi irẹlẹ ohun bẹbẹ lọdọ
rẹ; ki o si fifunni, ki awa ti n gba akara ati waini ẹda rẹ wọnyii, gẹgẹ bi idasilẹ
mimọ Ọmọ rẹ Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ni iranti iku oun iya rẹ, ki a le se alabapin
Ara oun Ẹjẹ rẹ ti o ni ibukun julọ; ni oru ọjọ na ti a fi i han, ẹni ti o mu Akara;
nigba ti o si ti dupẹ, o bu u, o si fi fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi pé, Gba, jẹ, eyi
yi ni Ara mi ti a fifun yin: Ẹ maa se eyi ni iranti mi. Bẹ gẹgẹ lẹhin Ounjẹ o gba
Ago; nigba ti o si ti dupẹ, o fifun wọn, wi pé, Gbogbo yin ẹ mu ninu eyi; nitori
eyi ni Ẹjẹ mi ti Majẹmu Titun, ti a ta silẹ fun yin ati fun ẹni pupọ fun imukuro
ẹsẹ: Nigbakugba ti ẹyin ba n mu u, ẹ ma se eyi ni iranti mi. Amin.

1. Nihin Alagba o gbe awo ni ọwọ rẹ;


2. Nihin ni yoo bu Akara;
3. Nihin ni yoo fi ọwọ le ori Akara gbogbo.
4. Nihin ni yoo gbe Ago ni ọwọ rẹ;
5. Nihin ni yoo fi ọwọ rẹ le ori gbogbo ohun elo, (bi o se Ago tabi Igo),
ti o ni waini ninu fun isọ-di-mimọ.

Ipinfunni Akara
ARA Jesu Kristi Olúwa wa ti a fifun ọ, ki o pa ara ati ọkan rẹ mọ titi iye ti
ko nipẹkun. Gba eyi jẹ, ni iranti pe Kristi ku fun ọ, ki iwọ ki o si ma fi oun se
Ounjẹ je ni okan rẹ ni igbagbọ, pẹlu idupe.

Ifi Ago funni


ẸJẸ Jesu Kristi Olúwa wa, ti a ta silẹ fun o, ki o pa ara ati ọkan rẹ mọ titi
iye ti ko nipẹkun. Gba eyi mu, ni iranti pe a ta ẹjẹ Kristi silẹ fun ọ, ki iwọ ki
o si ma dupẹ.

Nigba naa ni Alagba yoo gba Adura Olúwa, awọn eniyan yoo wi tẹle e
BABA wa ti mbẹ ni mbẹ, ki a bọwọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni
ki a se ni ayé, bi wọn ti n se ni ọrun. Fun wa ni Ounjẹ oojọ wa loni. Dari ẹsẹ wa
ji wa, Bi a ti n dari ẹsẹ ji awọn ti o sẹ wa. Ma fa wa sinu idẹwo; Sugbọn gba wa
lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, agbara ni tirẹ, lailai. Amin.

Lẹhin naa yoo si gbadura bayii


OLÚWA ati Baba mbẹ, awa onirẹlẹ ọmọ-ọdọ rẹ n fẹ ore rẹ bi ti Baba patapata,
ki iwọ ki o fi anu gba ẹbọ iyin ati ọpẹ wa yii; awa si n fi iparamọ buburu bẹbẹ
lọdọ rẹ lati fifunni, pe nipa itoye ati iku Jesu Kristi Ọmọ rẹ, ati nipa igbagbọ
ninu ẹjẹ rẹ, awa ati gbogbo Ijọ rẹ, ki a le ri imukuro ẹsẹ wa gba, ati gbogbo ore
miran ti o ti inu iya rẹ wa. Nihin yii, Olúwa, awa fi awa tikarawa, ọkan ati ara
wa fun ọ, lati se ẹbọ ti o yẹ, ti o mọ, ti o si se ẹbọ aye si o; awa si n fi
iparamọ bẹbẹ lọdọ rẹ, ki gbogbo wa, ti a se alabapin Idapọ mimọ yii, ki a le fi
ore-ọfẹ ati ibukun rẹ ọrun kun wa. Bi awa ko tilẹ ti yẹ, nitori ọpọlọpọ ẹsẹ wa,
lati ru ẹbọkẹbọ si o, sugbọn awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, ki iwọ ki o gba ise ati isin wa yi;
mase wọn itoye wa wo, bi ko se pe ki iwọ ki o dari ẹsẹ wa ji wa, nitori Jesu Kristi
Olúwa wa; nipasẹ ẹni, ati pẹlu ẹni, ni isọkan Ẹmi Mimọ, gbogbo ọla ati ogo wa fun
ọ, Baba Olodumare, ayé ainipẹkun. Amin.

Tabi eyi,
OLODUMARE ati lai Ọlọrun alaye, tọkan tọkan ni awa fi n dupẹ lọwọ rẹ, nitori
iwọ fi Ounjẹ ẹmi ti ara ati ẹjẹ iyebiye Ọmọ rẹ Olùgbàlà Jesu Kristi bọ awa, ti o
gba ohun ijinlẹ mimọ wọnyii bi o ti yẹ; ti o si fi bẹẹ mu ki ojurere ati ore rẹ si
wa, ki o da wa loju; ati pe eya ara Ijinlẹ ọmọ rẹ papa ni awa ise, eyini ni egbe
gbogbo awọn onigbagbọ alabukun fun, ti wọn si ise ẹni ireti ijogun ijọba rẹ ti ko
nipẹkun, nipa itoye iku ati iya iyebiye ti ọmọ rẹ ọwọn. Gidigidi ni awa si n fi
irẹlẹ bẹbẹ lọdọ rẹ, Baba mbẹ, ki iwọ ki o fi ore-ọfẹ rẹ ran wa lọwọ bẹẹ, ki awa ki
o le duro titi ninu ẹgbẹ mimọ naa, ki awa ki o si ma se iru ise rere wọnni, ti iwọ
ti la silẹ fun wa, lati ma rin ninu wọn; nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa, pẹlu iwọ ati
Ẹmi Mimọ , ẹni ti gbogbo ọla oun ogo wa fun, ayé ainipẹkun. Amin.

Nigba naa ni a o wi pé,

OGO ni fun Ọlọrun ni oke mbẹ, ati ni ayé alafia, ifẹ inu rere si eniyan. Awa yin ọ,
awa n fi ibukun fun ọ, awa n fori balẹ fun ọ, awa yin o logo, awa n dupẹ lọwọ rẹ
nitori ogo rẹ nla, Ọlọrun Olúwa, Ọba ọrun, Ọlọrun Baba Olodumare.
Olúwa, ọmọ bibi nikansoso naa Jesu Kristi; Ọlọrun Olúwa, Ọda-aguntan Ọlọrun, Ọmọ
Baba, ẹni ti o ko ẹsẹ ayé lo, saanu fun wa. ẹni ti o ko ẹsẹ ayé lo, saanu fun wa.
Ẹni ti o ko ẹsẹ ayé lo, gba adura wa. Ẹni ti o joko ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba, saanu
fun wa.
Nitori iwọ nikan ni mimọ; iwọ nikan ni Olúwa; iwọ nikan, Kristi, pẹlu Ẹmi
Mimọ, ni o ga julọ ninu ogo Ọlọrun Baba. Amin.

Ibukun
ALAFIA Ọlọrun ti o ta gbogbo oye eniyan yọ, ki o pa yin ni aya oun ọkan mọ ni
Imọ oun ifẹ Ọlọrun, ati ti Jesu Kristi ọmọ rẹ Olúwa wa; ati ibukun Ọlọrun
Olodumare, ti Baba, ti Ọmọ, ati ti Ẹmi Mimọ , ki o wa ninu yin, ki o si ma ba yin
gbe nigba gbogbo. Amin.

Adura
OLÚWA, fi anu ran wa lọwọ, ninu ẹbẹ ati adura wa wọnyii, ki iwọ ki o si fa
ọkan awọn ọmọ-ọdọ rẹ si ati ni igbala ti ko nipẹkun; ninu ayida ati agbako ayé iku
yi, ki a le ma dabo bo wọn titi nipa iranlọwọ ore-ọfẹ rẹ; nipasẹ Jesu Krisiti Olúwa
wa. Amin.
OLÚWA Olodumare ati ayérayé Ọlọrun, fiye si ni, awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, lati fi
ọna han wa, lati sọni di mimọ, ati lati se akoso ọkan ati ara wa, ni ọna ati ise
ofin rẹ; ati nipasẹ abo rẹ ti o lagbara julọ, nihin yii ati lai, ki a le ma pa wa
mọ ni ara ni ọkan; nipasẹ Jesu Kristi Olúwa ati Olùgbàlà wa. Amin.
ỌLỌRUN Olodumare, fifun wa awa mbẹbẹ lọdọ rẹ ki gbogbo ọrọ ti a fi ode eti wa
gbọ loni, nipa ore-ọfẹ rẹ, ki a gbin wọn si wa ni ọkan, ki wọn ki o le ma so eso
iwa rere ninu wa, fun ọla ati iyin Orukọ rẹ, nitori Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
OLÚWA, fi ore-ọfẹ rẹ julọ sanu wa ni gbogbo sisẹ wa, ki o si ma fi iranlọwọ
rẹ titi sun wa si iwaju; ni gbogbo ise wa ti a bẹrẹ si, ti a n se lọ, ti a si n se
pari lọdọ rẹ, ki awa ki o le ma yin Orukọ mimọ rẹ ni ogo, ati nikẹhin nipa anu rẹ,
ki a le ni iye ti ko nipẹkun; nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
ỌLỌRUN Olodumare, Olorisun ọgbọn gbogbo, iwọ ẹni ti o mọ aini wa ki a to
bere, ati aimọye wa ni ibere; Awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, ki iwọ ki o saanu ailera wa; ati
ohun wọnni, nitori alayé wa ti awa ko gbọdọ tọrọ, ati nitori ifọju wa ti awa ko le
bere, fiyesi lati fifun wa, nitori ẹyẹ ọmọ rẹ Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.
ỌLỌRUN Olodumare, iwọ ẹni ti o ti se ileri lati gbọ ẹbẹ awọn ti n tọrọ ni
Orukọ Ọmọ rẹ; Awa mbẹbẹ lọdọ rẹ, fi aanu de eti rẹ silẹ si awa ti n gbadura, ti a
si mbẹbẹ lọdọ rẹ nisinsin yii; ki o si fifunni, ki ohun wọnni, ti awa fi igbagbọ
bẹbẹ gẹgẹ bi ifẹ rẹ, ki a le ri wọn gba dajudaju, fun iranwọ aini wa, ati igbẹkẹle
ogo rẹ, nipasẹ Jesu Kristi Olúwa wa. Amin.

You might also like