You are on page 1of 3

O TU RUPO N ME JI

1
Paaka seyin kungii
O hogoji nle
A dia fun eniyan
A bu feniyan.
Won ni ki awon mejeeji o rubo.
Eniyan ni bi oun ba dele aye
Oun o maa ba ti gbogbo eniyan je ni.
Eniyan naaa ni bi oun ba dele aye tan
Ohun ti o ba wu oun ni oun o maa se.
Won ni ki oun naa o rubo.
Ko ru
Igba ti awon mejeeji dele aye tan
Lo ba di wi pe bi eeyan ba bimo sile tan
Eniyan o pa a.
Gbogbo nnkan ti eniyan ni
Ni awon eniyan mba a je.
Ni eniyan ba pada lo si oko alawo.
O loo rubo.
Won ni ki o loo da eegun.
Ni o ba bo sinu eku
O nlo koroo mo awon eniyan.
O ni bee gege ni awon awo oun wi.
Paaka seyin kungii
O hogoji nle
A dia fun eniyan
A bu feniyan.
Awon mejeeji ntikole orun bo waye.
Eniyan ni
Eniyan ni.
Eniyan won o jeniyan o nisimi.
2
Arojorojo imo
Osise bale re
A dia fun Gelelose
Ti nsawoo rode Apini.
Won ni Gelelose o o rire obinrin lode Apini
Sugbon ki o rubo.
O si ru u.
Igba o rubo tan
O si ba ire obinrin pade lode Apini.
O ni bee gege ni awon awo oun wi.
Arojorojo ewe
Arojorojo imo
Osise bale re
A dia fun Gelelose
Ti nsawoo rode Apini.
Gelelose gege
Iyawo pade okoo re lona.
3
Pepe, awo ile
Otita, awo ode
Alapaandede lo kole tan
Lo kojuu re sodoodo

Ko kanmi, ko kanke.
O waa kojuu re sodoodo
A dia fun Oyeepolu
Omo isoro nIfe
Eyi ti iyaa re o fi sile
Ni oun nikan soso lenje lenje.
Igba ti Oyeepolu dagba tan
Ko mo ohun oro ilee babaa re mo.
Gbogbo nnkaan re waa daru.
O wa obinrin, ko ri
Bee ni ko ri ile gbe.
Lo ba meeji keeta
O looko alawo.
Won ni gbogbo nnkan oro ilee babaa re
To ti gbagbe
Lo nda a laamu.
Won ni ki o lo
Si oju oori awon babaa re
Ki o maa loo juba.
Igba ti o se bee tan
Lo waa bere sii gbadun araa re.
O nlaje
O lobinrin
O si bimo pelu.
O ni bee gege ni awon awo oun wi.
Pepe, awo ile
Otita, awo ode
Alapaandede ko kole tan
Lo kojuu re sodoodo
Ko kanmi, ko kanke
O waa kojuu re sodoodo.
A dia fOyeepolu
Omo isoro nIfe
Oyeepolu o mokan.
Bepo le e koo taale ni
Emi o mo.
Boti le e koo fii lele ni
Emi o mo.
Boti le e koo taa le ni
Emi o mo.
Oyeepolu o mokan.
Gbogbo isoro orun
E sure wa
E waa gboro yi se.
4
Ologbon kan o ta koko omi seti aso
Omoran kan o moye eepee 'le
A dia fori
A bu funwa.
Ori ni ire gbogbo le to oun lowo bayii?
Won ni o rubo.
O si ru u.
Igba ti o rubo tan
O si ni gbogbo ire ti o nfe.
O ni bee gege ni awon awo oun
Nsenu reree pefa.
Ologbon kan o ta koko omi seti aso
Omoran kan o moye eepee 'le

A dia fori
A bu funwa.
Ori pele o
Ori abiye.
Eni ori ba gbeboo re
Ko yo.

You might also like