You are on page 1of 2

BABA OLORISUN IBUKUN GBOGBO

1. Baba olorisun ibukun gbogbo ,


Awa yin o fun ‘pade loni,
Jo f’orisun ibukun fun wa,
Orisun ‘bukun re ti ki gbe lai ,
Olorun abram , o d’owo re,
Nitori jesu masai gbo egbe wa.
2. Seri ‘bukun re sori gbogbo egbe,
At’igbimo l’okunrin, l’obirin ,
Egbe akorin ati gbogb’ osise,
To mbe ninu egbe serafu yi,
Olorun Aaron, o dowo re,
Di egbe serafu l’amure ododo.
3. Jo ma jeki fitila egbe yi ku,
Jo mase je k’ota le rig be se,
Jo tun gbogbo ibaje inu re se,
Je k’o gbile n’nu ‘fe oun ‘wa mimo,
‘wo oba sion, o d’owo re,
Jo ma je k’iyo egbe wa yi d’obu.
4. Bukun f’awon ati ore wa,
Omo egbe at’awon oworan,
Je ko ro wa , je k’ile roju fun wa,
K’a mase tori ara wa pose,
Jehovah salom, o d’owo re ,
Mu ki’paya lo k’alafia po si.
5. Siju anu re wo gbogbo egbe wa;
Dawo pasan ibinu re duro,
Darij’ awon ota at’elegan wa,
Mu ote at’ija kuro fun wa,
S’awotan arun to n ba ilu wa ja.
6. Baba, ma f’ebi keyin ayo fun wa,
K’a mase f’akisa pari aso,
Ma je ka f’arun pari ara lile ,
Ma je ki awa ku sowo esu,
Olorun hagar, o d’owo re,
Pese itura fun wa ni aye wa.
7. Jowo f’ike re ke awon alaisan ,
f’adun si f’awon t’aye won koro,
fi ire kun gbogbo awon ti ebi n pa;
jo ma je k’awon omo wa yanku,
jehova nissi, o d’owo re ,
masai j’opagun fun gbogb’ awon tire
8. ‘wo lo mu wa laye titi d’oni,
Je k’idasi wa je fun ogo re,
Lowo ewu at’ipalara gbogbo,
Jesu, masai fi iso re so wa,
Oyigiyigi, o d’owo re,
Pa mi mo ki n mase gb’ojo olojo lo.
9. Lojo ti a o se idajo aye,
T,awon angeli y’o wa kore fun o;
Gba wa, jesu, gba wa ni ojo nla na,
K’a wa le je ninu ire nla na,
Krist’ olugbala, o d’owo re,
Ma je ki n tase ibukun rere na.

You might also like