You are on page 1of 695

76

ORIN OWURO

1. C.M
Ago Re wonni ti li ewa to,
Oluwa awon omo Ogun
OD. 84:1

1 fp Olus‘agutan eni Re
Fi ara Re han wa,
‗Wo fun wa n‘ile adura
M‘okan wa gbadura

2. mf Fi ami ife Re han wa


So ireti wa ji
Se‘ri‘bukun Re s‘ori wa
K‘awa le ma yin O

3 mf K‘ife ati alafia


K‘o ma gbe ile yi!
F‘irora f‘okan iponju
M‘okan ailera le

4 mf F‘eti igbo, aya ‗gbase,


Oju ‗riran fun wa;
Tan imole Re lat‘oke
K‘a dagba l‘or‘ofe

5 mf K‘a fi gbagbo gbo oro Re


K‘a f‘igbagbo bebe
Ati niwaju Oluwa
K‘a se aroye wa.
Amin
2. 8.7.8.7
Oluwa fi igbala Re be mi wo OD 106:4

1 f Ife orun lail‘egbe,


Ayo orun sokale,
Fi okan wa se ‗bugbe Re,
Se asetan anu Re.

2 Jesu Iwo ni alanu


Iwo l‘onibu ife
cr Fi igbala Re be wa wo
M‘okan eru wa duro

3 mf Wa, Olodumare, gba wa


Fun wa l‘ore-ofe Re.
L‘ojiji ni k‘o pada wa,
Ma si fi wa sile mo;

4 f Iwo l‘a o ma yin titi,


Bi won ti‘nse ni orun
Iyin wa ki yoo lopin
A o s‘ogo n‘nu ‗fe Re.

5 cr S‘asepe awa eda Re


Je k‘awa lailabawon
K‘a ri titobi ‗gbala Re
Li aritan ninu Re.

6 f Mu wa lat‘ogo de ogo,
Titi di ibugbe wa;
Toa fi ade wa juba Re
N‘iyanu, ife, iyin.
Amin
3. L.M
Emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD 108:2

1 f Ji Okan mi, ba orun ji,


Mura si ise ojo Re.
Mase ilora, ji kutu.
K‘o san ‗gbese ebo oro

2 Ro gbogb‘ojo t‘o fi sofo


Bere si rere ‗se loni
Kiyesi ‗rin re l‘aye yi,
Ko si mura d‘ojo nla ni.

3 mf K‘oro re gbogbo j‘otito,


K‘okan re mo b‘osan gangan
Mo p‘Olorun nso ona re
O mo ero ikoko re.

4 f Nipa ‗mole ti nt‘roun wa


Tan ‗mole na f‘elomiran
Jeki ogo Olorun ‗han
Ninu ife at‘orun yin
5 f Ji, gbonranu ‗wo okan mi,
Yan ipo re l‘arin angeli‘,
Awon ti won nkorin iyin
Ni gbogbo igba s‘Oba wa.

6 f Mo ji, mo ji, ogun orun,


Ki isin yin s‘okan mi ji,
Ki nle lo ojo aye mi,
Fun Olorun mi bi ti yin.
AMIN
4. L.M
Ma rin niwaji mi, ki iwo ki o si pe.
Gen. 17:1

1 mf Oluwa mi, mo njade lo,


Lati se ise oojo mi;
Iwo nikan l‘emi o mo
Loro, lero, ati n‘ise

2 Ise t‘o yan mi l‘anu Re,


Jeki nle se tayo tayo,
Ki nr‘oju Re n‘nu ise mi,
K‘emi si le fi ‗fe Re han

3 Dabobo mi lowo danwo,


K‘opa okan mi mo kuro
Lowo aniyan aye yi
Ati gbogbo ifekufe.

4 cr Iwo t‘oju Re r‘okan mi,


Ma wa l‘ow‘otun mi titi,
Ki nma sise lo l‘ase Re,
Ki nfise mi gbogbo fun O.

5 mf Je ki nreru Re t‘o fuye,


Ki nma sora nigba gbogbo
Ki nma f‘oju si nkan t‘orun
Ki nsi mura d‘ojo‘ogo.

6 f Ohunkohun t‘O fi fun mi,


Je ki nle lo fun ogo Re,
Ki n f‘ayo sure ije mi,
Ki nba O rin titi d‘orun
AMIN
5 L.M
Nigbawo ni ikwo o to mi wa?
OD 101:2

1 mf Wa s‘odo mi, Oluwa mi,


Ni kutukutu owuro,
Mu k‘ero rere so jade,
Lat‘inu mi s‘oke orun

2 Wa s‘odo mi, Oluwa mi,


Ni wakati osan gangan;
Ki ‗yonu ma ba se mi mo,
K‘o si so osan mi d‘oru.

3 mp Wa s‘odo mi, Oluwa mi,


Nigbati ale ba nle lo,
Bi okan mi ba nsako lo,
Mu pada, f‘oju ‗re wo mi.

4 Wa s‘odo mi, Oluwa mi,


L‘oru, nigbat‘oru ko si,
P Je ki okan aisimi mi,
Simi le okan aya Re.

5 mp Wa s‘oso mi, Oluwa mi,


Ni gbogbo ojo aye mi,
p Nigbati emi mi ba pin
f Ki nle n‘ibugbe l‘odo Re.
AMIN
6 7.7.7.D
Sugbon orun ododo yio la fun eniyan ti O beru oruko Mi. Mal 4:2

1 f Krist‘t‘ogo Re ka aye,
Krist, Imole Otito;
Orun ododo dide,
K‘o si bori okunkun
‗mole ooro, sunmo mi,
‗Rawo oro yo n‘nu mi

2 mp Ooro to de laisi Re,


Ookun on ‗banuje ni,
Ile to mo ko l‘ayo,
Bi nko r‘oye anu Re,
B‘Iwo ko fi ‗mole Re
Kan oju on okan mi

3 mf Nje be okan mi yi wo,


Le okunkun ese lo,
F‘imole orun kun mi,
Si tu aigbagbo mi ka
Maa f‘ara Re han mi si
Titi di ojo pipe
AMIN
7 S.M.
Li ale, li owuro, ati li osan li emi o ma gbadura OD 55:17

1 mf Wa s‘adura ooro,
Kunle k‘a gbadura,
f Adura ni opa Kristian,
Lati b‘Olorun rin

2 mf L‘osan, wole labe


Apat‘ayeraye,
p Itura ojiji Re dun
Nigba t‘orun ba mu

3 mf Je ki gbogbo ile
Wa gb‘adura l‘ale;
Ki ile wa di t‘Olorun
di Ati ‗bode orun

4 p Nigbat‘od‘oganjo,
Je k‘a wi l‘emi pe,
f Mo sun, sugbon okan mi ji,
Lati ba O s‘ona
AMIN
8. C.M
Yi o fi iye Re bo o OD 91:4

1 mf Imole oro didun yi,


Ji mi nin‘orun mi,
Baba, ife Tire nikan,
Lo pa omo Re mo.

2 mp Nigbogbo oni, mo be O,
Maa se oluso mi,
Dariji mi, Jesu mimo,
Ki emi je Tire loni.

3 mf Wa se bugbe Re ninu mi,


Emi ore ofe,
So mi do mimo l‘aye yi,
K‘emi le roju Re.
AMIN
9 7.7.7.7.3
Ohun mi ni Iwo o gbo li owuro, Oluwa. OD 5:3

1 f Jesu, Orun ododo,


Iwo imole ife
‗Gbati ‗mole Owuro,
Ba nt‘ila orun tan wa,
Tan ‗mole ododo Re
Yi wa ka

2 mp Gege be iri ti nse,


S‘ori eweko gbogbo,
K‘Emi ore-ofe Re
S‘o okan wa di otun,
Ro ojo ibukun Re
p Sori Wa

3 mf B‘imole orun ti nran,


K‘imole ife Tire
Si ma gbona l‘okan wa,
K‘o si mu wa l‘ara ya
K‘a le ma f‘ayo sin O.
L‘aye wa.

4 Amona ireti wa,


Ma fi wa sile titi,
Fi wa s‘abe iso Re
Titi opin emi wa,
Sin wa la ajo wa ja
S‘ile wa

5 Ma to wa l‘ona toro
L‘ojo aye wa gbogbo
Sin wa la ekun re ja,
Mu wa de ‗le ayo na
cr K‘a le ba won mimo gba
p Isimi.
AMIN
10 6.6.6.6
Gbo ekun mi, Olorun; fiyesi adura mi.
OD 61:1

1 mp Baba mi, gbo t‘emi,


‗Wo ni alabo mi,
Ma sun mo mi titi,
Oninure Julo

2 Kristi Oluwa mi,


Iye at‘ogo mi,
Ki ‗gba naa yara de,
Ti un o de odo Re.

3 p Olutunnu julo,
‗Wo ti ngbe inu mi,
‗Wo t‘O mo aini mi,
Fa mi, k‘O si gba mi

4 mf Mimo, Mimo, Mimo,


Ma fi mi sile lae,
P Se mi ni bugbe Re,
Tire nikan laelae.
AMIN
11. C.M
Fi ona re le Oluwa lowo. OD 37:5

1 Lekan si, bi orun ti nran,


Awa mbe Olorun
Pe ki ‗mole Re ailopin
S‘amona wa loni

2 f K‘a mase da esekese,


K‘a ma si ro ibi;
K‘a ni otito gan l‘enu
Ati ife l‘okan

3 mf L‘ojo oni, Olugbala,


K‘a ri iranwo Re,
Di Lati gba wa lowo esu,
P Ti nd‘ode wa kiri

4 mf Ki ise wa l‘ojojumo
Ma je fun iyin Re,
Be l‘o ma mbukun ise wa
Ta mbere ninu Re.

5 cr Je ka fi iwontunwonsi
Kawo ‗fekufe wa,
Ki ‗gberaga asan ara,
Ma bori okan wa

6 f Olorun Baba at‘Omo


Ati Emi Mimo
Ni ki Eda at‘Angeli
F‘ogo ailopin fun.
AMIN
12 9.6.9.6
Abrahamu si sunmo odo Oluwa. Gen. 18:23

1 Je ki nsun mo O l‘ojojumo
Jesu Olugbala
Je ki ngb‘ara le O si, Jesu
Ni Gbogbo on li.

2 Je ki n fe Ewa Re han, Jesu,


Bi orun lo‘roke
Je ki ete mi so adun Re,
Pelu ayo toto,

3 Je ki ndabi orisun omi,


Jesu Olugbala
Ma lo mi l0jojumo, Jesu,
Fun ogo Re nikan

4 Lokan ati l‘ero mi, Jesu,


J‘oba patapata
Je ki njeni oloto, Jesu,
Si O l‘ohun gbogbo.

5 Monk‘ebi at‘ongbe Re, Jesu,


Ebi at‘okan wa;
Mo nsaferi ‗le mi ni Sion;
Nibit‘Olorun wa.
AMIN
13 8.7.11.8.7.11 & Ref
Olorun si wipe, Ki imole ki o wa; imole si wa. Gen. 1:3

1 mf ‗Mole wa l‘afonifoji
‗Mole wa l‘ori oke
Jesu l‘O mu wa s‘aye
Okukun yi,
‗Mole wa l‘ara itanna
To ndagba l‘eba odo,
Imole wa ni ‗bikibi ti mo nlo;
F ‗Mole, Mole t‘ife Re orun,
‗Mole, mole, itansan orun
‗Mole, mole, li aye wa yi,
‗Mole, mole, l‘ona ani
Gbogbo

2 mf Imole wa lori pada


Ati l‘ori koriko
Nibiti awon eye nkorin iyin;
Imole wa lori oke,
‗Mole wa ni petele
Je ki gbogbo eda jumo korin
‗yin

3 f B‘aye tile kun fun ‗mole


To si ntan l‘ojojumo,
Okan pupo wa n‘nu okunkun Sibe,
Ti ko gb‘oruko Jesu ri,
Tabi ife ‗yanu Re,
Je ki a fi oro Re ran won
L‘owo
AMIN
14 C.M
Emi dubule, mo si sun‘ mo si ji;
Nitori ti Oluwa ti mi l‘ehin. OD 3:5

1 mf Ninu gbogbo ewu oru,


Oluwa l‘o so mi;
Awa si tun ri ‗mole yi
A tun te ekun ba.

2 Oluwa, pa wa mo l‘oni,
Fi apa Re so wa;
Kiki awon ti‘wo pamo,
L‘o nyo ninu ewu.

3 K‘oro wa, ati iwa wa,


Wipe, tire l‘awa;
Tobe t‘imole otito
Le tan l‘oju aye.

4 mp Ma je k‘a pada lodo Re,


Olugbala owon;
Titi ao f‘oju wa ri
Oju Re li opin.
AMIN
15 6.6.11.D
A ti tan ife Olorun ka okan wa lati odo Emi Mimo wa ti a fi fun wa. Rom. 5:5

1 mf Ife orun Sokale,


Tan ka okan mi yi,
Ki o si f‘ore-ofe Re gbogbo
Be wo;
F Olutunu Orun,
Mf Farahan n‘n‘Okan mi,
Si mu ki ina mimo Re mu soji

2 mf Je ko ma jo gere,
Ki ‗fekufe d‘eru
T‘ise iyangbo ni waju afefe;
F Ki ‗mole ologo
Mf Tire tan yi mi ka,
Si ona mi ati aye mi gbogbo

3 mf Fi ife mimo se
Ewu agbada mi;
Ati iwa ‗rele, awotele mi;
F Fokan mimo toto
Mf Ti irele okan
Mp Tinsokun fun ese mi gbogbo
Kun mi

4 mf ‗Gbana okan mi yi
Y‘o di alagbara
Lati se ‗fe Re ju b‘a ti lero lo;
F Ko s‘eda na t‘o mo
Tor‘ofe okan wa
Mf Titi y‘o fi di ite Emi mimo.
AMIN
16 L.M
Emi o ma fi otito re han lati irandiran. OD 89:1

1 f Baba, a sope ‗toju Re,


T‘o f‘alafia kun ‗le wa;
Odo Re ni won ti san wa
Owo Re l‘o si ngbe won ro

2 mf Olorun, t‘o ye k‘a ma yin,


L‘a nkepe ninu ile wa;
Oluwa orun, ti ko ko
Lati ma gbe ile aye.

3 Jek‘olukuluku ‗dile
Ma kepe O tosan-toru;
K‘a ko omo at‘om‘odo
L‘ofun at‘ore-ofe Re.

4 f Beni k‘iran ti mbo ma so


T‘ola ooko Re t‘o logo,
Titi gbogbo wa y‘o fi lo
Dapo mo idile t‘orun
AMIN
17 C.M
Ona mi iba je la sile lati ma pa olana Re Mo! OD119:5

1 mf Oluwa, emi y‘o korin


Anu at‘idajo;
Nigbawo n‘Iwo y‘o fun mi
N‘imole on iye

2 mo nfe lati t‘ona pipe,


Ki nni okan pipe,
Ona, okan ati ile,
Nibiti Iwo mbe,

3 Mo nfe ki awon oloto


Je oluranwo mi;
Ki nfi won s‘ore-imule
A t‘omo-odo mi.

4 cr Ki yo si eke at-etan
Ninu ibugbe mi;
Mp Oluwa, Jek‘Ibugbe mi
Ye fun O lati gbe!
AMIN
ORIN ALE

18 8.7.8.7
Emi o ma korin anu Oluwa lailai. OD 89:1

1 f L‘ojojumo l‘a ngbe O ga


Nigbati ile ba mo,
T‘a ba kunle lati yin O
Fun anu ti owuro

2 L‘ojojumo l‘angbe O ga
Pel‘orin n‘ile-eko,
Lojojumo, pelu iyin,
L‘a nse ise wa gbogbo.

3 L‘ojojumo l‘a ngbe O ga


Ninu orin k‘a to sun
Awon Angel‘gbo, won si nso
Awon aguntan Kristi

4 L‘ojojumo l‘a ngbe O ga


Ki se ni iyin lasan;
Otito ati igboran
Nf‘ogo Re han ninu wa.

5 mf L‘ojojumo l‘a ngbe O ga


Gba t‘a ngbiyanju fun krist‘
Lati ma farada iya
K‘a pa ese run n‘nu wa.

6 f L‘ojojumo l‘a ngbe O ga


Tit‘ ojo wa y‘o fi pin
Tao simi n‘nu lala gbogbo
L‘alafia d‘ojo Re
AMIN
19 L.M
Nigbati iwo ba sun, yio ma so O. Owe 6:22

1 f Ogo f‘Olorun l‘ale yi


Fun gbogbo ore Imole,
So mi, Oba awon Oba
L‘abe ojiji iye Re.

2 mp Oluwa f‘ese mi ji mi,


Nitori omo Re, loni
K‘emi le wa l‘alafia,
Pelu iwo ati aye

3 mf Je k‘okan mi le sun le O,
K‘orun didun p‘oju mi de,
Orun ti y‘o m‘ara mi le,
Ki nle sin O li owuro

4 mp Bi mo ba dubule laisun,
F‘ero orun kun okan mi,
Ma je ki nl‘ala bururu,
Ma je k‘ipa okun bo mi

5 ff Yin Olorun, Ibu ore;


E yin, eyin eda aye,
E yin, eyin eda Orun,
Yin Baba, Omo on Emi
AMIN
20 6.4.6.6
Je ki adura mi ki o wa si iwaju Re bi ebo asale. OD 141:2

1 mp Orun fere wo na,


Ojo lo t
Cr K‘ife k‘o ji dide
Ko rubo asale

2 pp Bi Jesu l‘origi,
Ti teriba,
T‘O jowo emi Re
Le Baba Re lowo

3 mf Be ni mo f‘emi mi
Fun l‘a fun tan,
Ni ‗pamo re mimo
L‘emi gbogbo sa wa

4 mp Nje emi o simi


Lodo Re je,
Laije k‘ero kan so
Yo okan mi lenu

5 ‗Fe Tire ni sise


L‘onakona;
Mo d‘oku s‘ara ni
Ati s‘ohun gbogbo

6 mf Be l‘emi ye; sugbon


Emi ko, On
Ni mbe laye n‘nu mi,
L‘agbara ife Re.

7 f Metalokan mimo,
Olorun kan
Lae ki nsa je Tire
K‘On je t‘emi titi

AMIN
21 8.7.8.7.7.7
Eni ti npa o mo ki yio togbe. Od. 121:3

1 f Ife Re da wa si loni,
Lare, a si dubule,
Ma so wa ni ‗dake oru,
K‘ota ma yo wa l‘enu
Jesu, se Olutoju wa;
Iwo l‘o dun gbekele

2 Ero at‘elajo l‘aye


A ngb ‗arin awon ota;
Yo wa, at‘ile wa l‘weu;
Lapa Re ni ka sun si;
P N‘ijo iyonu aye pin;
K‘a le simi l‘odo Re

AMIN
22 10.10.10.10
Ba wa duro: nitori o di ojo ale. Lk 24:29

1 mf Wabami gbe, ale fere le tan;


Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe
Bi Oluranlowo, miran ba ye,
Iranwo alaini, Wa ba mi gbe.

2 p Ojo aye mi nsare lo s‘opin


Ayo aye nku, ogo re nwomi,
Ayida at‘ibaje ni mo n ri,
cr ‗Wo ti ki yipada, wa ba mi gbe.

3 mp Ma wa l‘eru b‘Oba awon oba


B‘oninure, wa pelu ‗wosan Re,
Ki O si ma kanu fun egbe mi,
Wa, Ore elese, wa ba mi gbe.

4 Mo n fe O ri, ni wakati gbogbo


Kilo le segun esu b‘ore Re?
Tal‘o le se amona mi bi Re?
N‘nu ‗banuje at‘ayo ba mi gbe.

5 mf Pelu ‗bukun Re, eru ko ba mi


Ibi ko wuwo, ekun ko koro,
F Oro iku da? Segun isa da?
Un o segun sibe, b‘Iwo ba mi gbe

6 p Wa ba mi gbe, ni wakati iku,


Cr Se ‗mole mi si toka si orun
F B‘aye ti nkoja, k‘ile orun mo,
Fp.mp Ni yiye, ni kiju, wa ba mi gbe.
AMIN
23 L.M
Emi o dubule pelu li alafia, emi o si sin. OD 4:8

1 mf Iwo imole okan mi,


Ni odo Re, oru ko si,
Ki kuku aye ma bo O,
Kuro l‘oju iranse Re.

2 pp Ni gbat‘orun ale didun


Ba npa ipenpe ‗ju mi de,
K‘ero mi je lati simi,
Lae l‘aya Olugbala mi.

3 mf Ba mi gbe l‘oro tit‘ale


Laisi Re, emi ko le wa,
P Ba mi gbe ‗gbat‘ile ba nsu,
Laisi Re, emi ko ke ku.

4 mp Bi otosi omo Re kan


Ba tapa s‘oro Re loni,
Cr Oluwa, sise ore Re,
Ma je k‘o sun ninu ese

5 mf Bukun fun awon alaisan,


Pese fun awon talaka,
Di K‘orun onirobinuje
Pp Dabi orun omo titun

6 cr Sure fun wa ni gbat‘a ji


Ka to m‘ohun aye yi se
F Titi awa de ‗b‘ife
Ta o si de Ijoba Re.
AMIN
24 L.M
Nigbati o di asale, nwon kogbogbo Awon Alaisan to o wa. MK 1:32

1 mf L‘oju ale ‗gba‘t orun wo,


Won gbe abirun w‘odo Re,
P Oniruru ni asisan won,
F Sugbon won f‘ayo lo‘ le won

2 mf Jesu l‘ oj‘ale yi,


A sun m‘O t‘awa t‘arun wa,
Cr Bi a ko tile le ‗ri O,
Sugbon, a mo p‘O sunmo wa.

3 mp Olugbala, wo osi wa,


Opo nsaisan, opo nk‘edun,
Opo ko ni ‗fe si O to.
Opo n‘ife won si tutu.

4 Opo ti ri p‘asan l‘aye


Sibe nwon ko f‘aye sile,
Opo l‘ore b n‘inu je,
Sibe won ko fi O s‘ore

5 Ko s‘okan ninu wa t‘o pe


Gbogbo wa si ni elese,
Awon t‘o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe

6 mf Sugbon Jesu, Olugbala,


Eni bi awa ni ‗Wo se
‗Wo ti ri‘danwo bi awa
‗Wo si ti mo ailera wa.

7 Agbar‘owo Ro wa sibe,
Ore Re si ni agbara,
P Gbo adura ale wa yi,
Cr Ni anu, wo gbogbo wa san.
AMIN
25 10.10.10.10
Emi o dide, emi o si to baba mi lo. LK 15:18

1 mp Baba, a tun pade l‘oko Jesu,


A si wa teriba lab‘ese Re,
A tun fe gb‘ohun wa s‘oke si O
Lati wa anu, lati korin ‗yin

2 f Ayin O fun itoju ‗gba gbogbo


Ojojumo l‘a o ma rohin ‗se Re,
Wiwa laye wa, anu Re ha ko
Apa Re ki O fi ngba ‗ni mora.

3 p O se! A ko ye fun ife nla Re,


A sako kuro lodo Re poju,
Mf Sugbon kikan kikan ni o si npe
Nje a de a pada wa ‗le Baba

4 mp Nipa ooko t‘ob‘or‘ohun gbogbo


Nipa ife t‘o ta‘fe gbogbo yo
Nipa eje ti a ta fun ese,
Cr Silekun anu, si gba ‗ni s‘ile
AMIN

26 10.4.10.4.10.10
Li osan pelu, o fi awosanma se amona Won ati li Oru
Gbogbo pelu imole ina

1 mp ‗Wo imole larin okun aye,


Ma sin mi lo;
Okunkun su, mo si jinna s‘ile,
Ma sin mi lo;
Cr Nko s‘aferi ola bi y‘o ti ri,
To ese mi, ‗sise kan to fun mi,

2 p Nigba kan ri, emi ko be O pe


K‘O sin mi lo,
Beni nko fe O, sugbon nigba yi,
Ma sin mi lo,
Afe aye ni mo si nto leyin,
Sungbon Jesu, ma ranti igba ni.

3 mf Ipa Re l‘o ti nid mi mu, y‘o si Ma sin mi lo.


Ninu ere ati yangi aye,
Ma sin mi lo
Titi em‘o fi ri awon wonni
Ti mo fe, ti won ti f‘aye sile

AMIN
27 8.7.8.7
Kiyesi, eniti npa Isreali mo kii togbe, Beni Ki I sun. OD 121:4

1 mp K‘a to sun, Olugbala wa,


Fun wa n‘ibukun ale,
A jewo ese wa fun O,
Iwo l‘O le gba wa la.

2 cr B‘ile tile ti su dudu,


Okun ko le se wa mo,
Mf Iwo Eniti ki ‗sare,
Nso awon eniyan Re.

3 p B‘iparun tile yi wa ka,


Ti Ofa nfo wa koja,
Mf Awon Angeli yi wa ka,
P Awa o wa lailewu.

4 p Ma ko wa, ma fi wa sile,
K‘agbara wa di otun,
Ki imole oro ji wa,
E K‘a le ma fe ise Re.

5 N‘irele awa fara wa,


S‘abe abo Re, Baba,
Jesu, ‗Wo t‘O sun bi awa,
Se orun wa bi tire

6 Emi mimo, rado bo wa,


Tan‘ mole s‘okunkun wa,
Cr Tit‘awa o fi ri ojo
F Imole ayeraye.
AMIN

28 8.8.8.D
Nitori Oluwa yio je imole ainipekun Fun O. Isa. 60:20

1 mf Jesu, bukun wa k‘a to lo,


Gbin oro Re si wa lokan;
K‘o si mu k‘ife gbigbona
Kun okan ilowowo wa,
Cr Nigba yiye at‘iku wa,
P Jesu jare, se ‗mole wa.

2 mp Ile ti su, orun ti wo,


‗Wo si ti siro iwa wa,
Die nisegun wa loni,,
Isubu wa lo p‘apoju
3 mf Jesu, dariji wa, fun wa
L‘ayo ati eru mimo
At‘okan ti ko l‘abawon,
Ka ba le jo Ol‘ajo tan.

4 mp Lala dun, tori‘Wo se ri;


Aniyan fere, O se ri,
Ma je k‘a gbo t‘ara nikan,
K‘a ma bo sinu idewo

5 mp A mbe O ‗awon alaini,


F‘elese at‘awon t‘a fe,
Je ki anu Re mu wa yo,
‗wo Jesu l‘ohun gbogbo wa.

6 mf Jesu bukun wa, ile su,


Tikara Re, wa ba wa gbe,
Angel‘ ere nso ile wa
A tun f‘ojo kan sunmo O
AMIN

29 9.8.9.8
Ati lati duro li orowuro lati dupe, ati lati Yin Oluwa ati be gege li asale. I Kro. 23:30

1 mf Oluwa, ojo to fun wa pin,


Okunkun si de l‘ase Re,
‗Wo l‘a korin owuro wa si,
Iyin Re y‘o m‘ale wa dun.

2 mf A dupe ti ijo Re ko sun,


B‘aye ti nyi lo s‘imole,
O si nsona ni gbogbo aye,
Ko si simi t‘osan-t‘oru.

3 B‘ile si ti nmo l‘ojojumo,


Ni orile at‘ekusu,
Ohun adura ko dake ri,
Be l‘orin iyin ko dekun

4 Orun t‘o wo fun wa, si ti la,


S‘awon eda iwo-orun,
Nigbakugba li enu si nso
Ise ‗yanu Re di mimo

5 cr Be, Oluwa, lae n‘Ijoba Re,


Ko dabi ijoba ye;
F O duro, o si nse akoso,
Tit‘ida Re o juba Re.
AMIN
30 7.6.7.6.8.8
Nitori ojo nlo. Jer. 6:4
1 Ojo oni koja lo,
A dupe, Oluwa,
Jo, gba wa lowo ese
Ni wakati oru,
Di Jesu, jo, f‘iso Re so wa,
Cr Si mu wa la oru yi ja.

2 mf Ayo oni koja lo,


A gb‘okan wa s‘oke
Jo, ma je k‘a n‘ikose
Ni wakati oru;
Di Jesu, jo fun wa n‘imole,
Cr Si mu wa la oru yi ja

3 mf Lala oni koja lo,


A fi orin yin O,
Jo, ma je k‘a ri ewu
Ni wakati oru;
Di Jesu, jo f‘is Re so wa,
Cr Si mu wa la oru yi ja.

4 mf S‘Olupamo wa, Baba,


Nitori; Wo l‘O mo
Gege b‘ewu ti po to,
Ti a o ba pade;
Di Jesu, Olufe, gbo ti wa,
Cr Si mu wa la gbogbo won ja.
AMIN

31 8.8.8.4
Oorun ki yio pa o nigba Osan, tabi osupa nigba oru. OD 121:6
1 mf Oro didan ti rekoja;
Wawa l‘akoko na fo lo,
Di Bi osan si ti nkoja lo,
Nile nsu bo.

2 mf Kukuru, l‘ojo aye wa,


Were l‘osan re nde opin;
Krist‘ Wo ti se Ona iye,
Sin wa de ‗le.

3 cr Jo fi ore-ofe Re nla
Gbe okan wa b‘ilu t‘erun;
Je k‘a ma wo ‗le didan ni
Ti mbe l‘oke.

4 f Nibi ‗mole, iye ayo


At‘ alafia gbe njoba,
T‘awon angel‘ ko dekun ‗ko
Orin iyin.

5 f T‘awon mimo wa ‗so ala,


Ti okunkun ale ki su,
Ti ‗Wo ‗Mole ayeraye
Je Oluwa.
AMIN

32 8.3.3.8
Emi o ma yin O tinu-tinu mi gbogbo. OD 138:1

1 mp Ki nto sun, fun ore t‘oni


T‘Olorun
Se fun mi,
Cr Un o yin Olugbala

2 mf Oluwa, kini un o fi yin


Oko Re,
T‘o kun fun
Anu ati Ore.

3 mf Iwo ti s‘eto irin mi,


L‘ona Re
Di ‗ Wo gb‘ebe;
‗Wo si gba ise mi

4 mp Ma ko mi, ma fe mi titi;
F‘alafia
Re fun mi,
Titi ‗Wo y‘o pe mi

5 mf ‗Wo apata at‘odi mi,


F‘ipa Re
Pa mi mo
‗gba m‘ba dubule sun.

6 p Nigbakugba ti mo ba ku,
Cr Je k‘emi
Ji dide
F Pelu awon mimo.
AMIN

33 7.7.7.7.7.7
Iwo o pa mo li alafia pipe, okan eniti o simi le O. Isa. 26:3

1 mf L‘alafia l‘olorun
Sin wa ja ose miran;
E je k‘a bere ‗bukun
L‘ojo ‗simi ti mbo yi,
Ojo t‘o tobi jule,
Apere ayeraye.

2 f K‘a sope opo aanu


Ti a ri gba l‘ose yi;
Olodumare so wa,
O bo wa, O si to wa,
Di B‘a ti s‘alaimore to,
Ta nfi ese s‘esan fun.

3 mp B‘a ti ntoro ifiji


L‘oruko Olugbala,
Fi oju anu Re han,
Le Ese on ‗tiju lo,
Gba wa lowo aniyan
K‘a le sun l‘alafia.

4 mf ‗Gbati ile ba si mo,


Je k‘a mo p‘o wa n‘tosi
Je k‘a le ri ogo Re
‗Gbat‘a be de ile Re,
Cr Nibe, Oluwa fun wa
N‘itowo ase orun

5 mf Jek‘iro ‗hinrere Re
Gb‘elese at‘oloto;
Cr K‘eso or‘ofe ma po,
K‘o tan gbogbo arun wa,
F K‘ojo ‗simi ma ri be
Tit‘ao de ijo t‘orun

34 7.7.7.7.4 & Ref


Emi o gbe leke, nitori ti o mo oruko mi. OD 91:14

1 mf Orun ti de iwo re,


‗simi nt‘orun bo w‘aye;
Wa ka josin bi ale
Ti ntan ‗na fitila re
Loju sanma
Mp Mimo, mimo, mimo Oba Ogo,
Torun-taye kun fun O,
F Torun-taye l‘o nyin O,
Oga ogo

2 mp Oluwa iye, labe


Orun ti se ‗bugbe Re,
Ko awa ti nw‘oju Re
Jo sin‘agbo ife Re;
‗Wo mbe n‘tosi.
3 Bi ile si ti nsu lo,
‗Wo t‘o f‘ife d‘aye mu
L‘okan wa nwa, rekoja
Ogo at‘ewa ‗rawo
To boju Re.

4 mf Gba irawo at‘osan,


At‘oru ki o si mo,
Oluwa awon agenl‘,
Je kari ‗mole aye
Ki okun pin.
AMIN

35 7.7.7.7
Iwo ti ngbo adura, si odo re ni gbogbo eniyan mbo. OD 65:2

1 mf Agboju s‘oke si O,
At‘owo ati okan;
Tewogba adura wa,
P B‘o tile se ailera.

2 Oluwa je k‘a mo O,
Je k‘a mo oruko Re;
Je k‘awa se ife Re,
Bi won ti nse li orun

3 mp Nigbati a sun l‘oru


So wa k‘o duro ti wa;
F Nigbati ile si mo,
Ff K‘a ji, k‘a fi ‗yin fun O.
AMIN

36 6.5.6.5
Jesu si duro larin, O ni, ‗Alafia fun Nyin‘. Jn., 20:26
1 mf Jesu wa s‘arin wa,
L‘agbar‘ajinde,
Je k‘isin wa nihin
Je isin owo.

2 mp Mi Emi Mimo Re
Sinu okan wa,
Cr Mu ‗foya at‘aro
Kuro lokan wa.

3 f Bi a ti nyara lo,
L‘ona ajo wa,
K‘a ma sona f‘oro
T‘ojaeraye.
AMIN
37 13.10.13.10
E ma sin Oluw Ewa iwa mimo. OD 96:9

1 mf E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo


Wole fun k‘esi pokik‘ ogo Re
Pelu wura ‗gboran ati turari ‗rele
W wole fun Un k‘e si juba Re.

2 Gbe eru aniyan yin lele lese Re


Y‘o si ti ka Re ba yin gbe d‘ori;
Y‘o tu o ninu, yo si gbo adura re,
Y‘o to ‗sise re bo ti to fun o

3 Ma beru lati wo agbala Re, pelu


Kiun ninu oro t‘o le pe n tire;
Cr Ewa otito ati ife owuro,
F ebo wonyi la nbere lowo re

4 mf B‘a tile m‘awon wonyi wa ni ‗wariri


Cr On y‘o gba won l‘oruko to sowon,
F ayo owuro y‘o dipo ekun ale
Ireti kikun y‘o dipo eru.

5 mf E sin Oluwa ninu ewa iwa mimo,


Wole fun k‘e si pokik‘ogo Re
Pelu wura ‗gboran ati turari ‗rele.
E wole fun Un ke si juba Re.
AMIN

38 C.M
E wa, e je ki a korin si Oluwa. OD95:1
1 mf E wa k‘a korin s‘Oluwa,
Olukuluku wa;
F Ki a ho iho ayo si
Apata ‗gbala wa.

2 e je k‘a wa siwaju Re
Pelu ‗yin at‘ope;
Ka ko orin pel‘ore ofe,
Ka si yo ayo nla.

3 ff Olorun yi tobi l‘Oba


J‘awon orisa lo;
Gbogbo‘aye wa nikawo Re
At‘awon oke nla

4 f Tire li awon okun nla,


On ni O si da won;
Ati ‗yangbe ile pelu,
Owo Re lo si da.
5 mf E wa, e je ki a wole
Ki a teriba fun,
Ki a si kunle niwaju
Oluwa Eleda.

AMIN

39 S.M & Refrain


Eniti enyin fe lairi. 1 Peter 1:8
1 f Eyin te fe Oluwa,
E fi ayo yin han,
E jumo ko orin didun,
E jumo ko orin didun
K‘e si y‘ite na ka,
K‘e si y‘ite na ka
Ff A nyan lo si Sion‘
Sion‘ to l‘ewa jule
A nyan goke lo si Sion‘,
Ilu Olorun t‘o l‘ewa

2 f Je k‘awon ni ma korin
Ti ko m‘Olorun wa,
Sugbon awon omo Oba,
Sugbon awon omo Oba,
Y‘o royin ayo won,
Y‘o royin ayo won.

3 Oke Sion‘l‘o nmu


Egberun adun wa
Ki a to de gbangba orun
Ki a to de gbangb‘orun
Pelu ‗ta wura re,
Pelu ‗ta wura re.

4 mf Nje ka ma korin lo,


Cr K‘omije gbogbo gbe
F A nyan n‘ile Immanuel‘
A nyan n‘ile Immanuel‘,
Ff S‘aye didan loke,
S‘aye didan loke
AMIN

40 D.S.M
Eniti enyin fe lairi. 1 pet 1:8

1 f Eyin t‘e f‘Oluwa,


E fi ayo yin han;
E jumo ko orin didun
B‘e ti ny‘ite Re ka;
Jek‘awon ‗ni dake
Ti ko m‘Olorun wa;
Sugbon k‘awon ‗ranse Oba
Ma ro ayo won ka.

2 Olorun t‘o joba,


Ti nwo gbogbo aye
Ti ngu awosanmo l‘esin
Ti nmu ‗ji pa roro;
Ff Tiwa l‘Olorun yi
Baba Olufe wa;
Y‘o ran agbara t‘orun wa
Lati gbe wa soke

3 mf Nibe, l‘ao r‘oje Re,


T‘a ki o dese mo;
T‘ao si ma jadun ailopin,
Nipa or‘ofe Re;
Cr Loto, k‘a to jinde
Si iye ailopin,
Ero irora nlanla na
F Ninu Ayo wa bi si.

4 Eni-or‘ofe ri
‗Bere ogo laye;
Eso orun ngberu laye
N‘nu gbagbo on ‗reti:
Cr Nje k‘orin wa goke,
K‘omije gbogbo gbe;
F A nkoja lo n‘le ‗manuel‘
S‘aye rere loke.

AMIN

41 13.9.13.9 & Ref.


E ma ba ara nyin soro ninu psalmu, ati orin iyin ati orin Emi. Efe. 5:9
1 mf Ko su wa lati ma ko orin igbani
F Ogo f‘Olorun aleluya!
A le fi igbagbo korin na s‘oke kikan.
f Ogo f‘Olorun aleluya!
A le fi igbagbo korin na s‘oke kikan.
Ff Ogo f‘Olorun, Aleluya
Mf Omo Olorun ni eto lati bu s‘ayo
Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns‘aferi Re;
Nigb‘o se a o de afin Oba wa Ologo
F Ogo f‘Olorun, Aleluya!

2 mf Awa mbe n‘nu ibu ife t‘o ra wa pada,


F Ogo f‘Olorun Aleluya!
Mf Awa y‘o fi iye goke lo s‘oke orun;
F Ogo f‘Olorun, Aleluya!

3 mf Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,


F Ogo f‘Olorun Aleluya!
Nibiti ao ri Oba Ogo n‘nu ewa Re,
Ff Ogo f‘Olorun, Aleluya!

4 mf Nibe ao korin titun t‘anu t‘O Da wa n de,


F Ogo f‘Olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin
‗yin ti Krist;
Ff Ogo f‘Olorun, Aleluya!
AMIN

42 C.M
Eyi li ojo ti Oluwa da. OD 118:24
1 mf Wa, je k‘a jumo f‘ohun kan
Korin yi ite ka;
Oni l‘ojo t‘Oluwa da
T‘o si pe ni Tire.

2 f Ojo yi l‘Olorun bukun,


Larin ojo meje;
Apere ‗simi ailopin
T‘awon t‘orun ngbadun,

3 Nje k‘a ma korin oko Re


K‘a ma reti ojo
T‘Oludande y‘o sokale
T‘asan aye y‘o pin.

4 Lojojumo titi aye


Ni ki a ma korin;
K‘a ma yo ninu Oluwa
Titi ayeraye.
AMIN

43 L.M
Oluwa yio fun ni li ore-ofe ati ogo: ko si ohun rere ti yio fa
Sehin lowo awon ti nrin dede. OD 84:11
1 mp Oluwa gbo adura wa
N‘nu le Re l‘ojo mimo li;
Bi ebo ope n‘ile yi
K‘orin wa je itewogba.

2 cr Oluwa, isimi Re dun


Sugbon t‘oke ju t‘aye lo; Sibe
Pelu ‗reti ayo
Li okan ongbe wa nsare.
3 mf Ko si are, ko si ise,
Ese, iku ki y‘o de ‗be,
Ohun irora ki y‘o dun
Nibiti ahon aiku wa.

4 f Ko si adagiri ota,
Isimi laisi aniyan,
Oju ojo ko su nibe,
Osan gangan ayeraye.

5 mf Bere, Ojo t‘a ti nreti,


Mo si aye irora yi,
Ao f‘ayo rin l‘ona t‘ayo
Ao si sun ninu Oluwa
AMIN

44 7.6.7.D.
Mo wa ninu emi li ojo Oluwa. Ifi. 1:10
1 f Ojo ‗simi at‘ayo
Ojo inu didun,
Itunu fun ‗banuje
Ojo dida julo,
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re,
P Nko Mimo, Mimo, Mimo,
S‘Eni Metalokan.

2 f L‘ojo yi n‘imole la,


Nigba dida aye,
Ati fun igbala wa,
Krist‘ jinde n‘nu oku
Mf L‘ojo yi li Oluwa
Kan Emi t‘orun wa,
Ojo Ologo julo
T‘a tan ‗mole pipe

3 mf Ebute abo ni O
Larin iji aye;
Ogba didara ni O
Nib‘omi iye nsan
Orisun ‗tura ni O
Laye aginju yi;
L‘ori re, bi ni pisga
L‘a nwo ‗le ileri.

4 mp L‘oni s‘ilu t‘ara nu


Ni manna t‘orun nbo
Si ipejopo mimo
N‘ipe fadaka ndun,
N‘ibiti ihinrere
Ntan imole mimo
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara.

5 k‘a r‘ore-ofe titun


L‘ojo ‗simi wa yi
K‘a si de ‗simi t‘o ku
F‘awon alabukun,
Nie k‘a gbo ‗hun soke
Si Baba at‘Omo;
Ati si Emi Mimo
N‘iyin Metalokan.
AMIN

45 L.M
Nitori omo eniyan je Oluwa ojo isimi. Mat. 12:8

1 f Oluwa ojo Isimi


Gbo eje wa nihin, loni,
Gba orin iyin ti a nko
Be ebo ope wa si O

2 A fe isimi t‘aye yi
Sugbon ‗simi t‘orun dun ju;
Eyi ni l‘okan wa nle pa;
Pelu itara on ife.

3 mf Ko saare mo tab‘iponju
Ese tab‘egbe kio de ‗be;
Ose ki y‘o dapo merin
Ti awon eni aiku nko

4 ko si idagiri ota,
Beni ko s‘ipaya nibe;
Ko si oru, ko s‘ikuku;
Mf Afi osan titi lae lae.

5 Bere, Ojo t‘a ti nreti,


Afemoju re l‘a fe ri,
A fe yo! Lona ise yi
K‘a si de ibi ‗simi na.
AMIN

46 6.6.6.6.D
Oni li ojo isimi fun Oluwa. Eks. 16:25
1 mf Jesu, a fe pade
L‘ojo re mimoyi,
Mf A si ‗ite Re ka
L‘ojo Re mimo yi
Ff Wo ore wa orun,
Adura wa mbo wa,
Mf Bojuwa emi wa,
L‘ojo Re mimo yi.

2 f A ko gbodo lora
L‘ojo Re mimo yi
Li eru a kunle
L‘ojo Re mimo yi
Ma to gbogb‘ero wa,
K‘Iwo k‘o si ko wa
K‘a sin O b‘oti ye
L‘ojo Re mimo yi.
3 f A teti s‘oro Re
L‘ojo Re mimo yi,
Buku oro t‘a gbo
L‘ojo Re mimo yi,
Ff Ba wa lo ‗gbat‘a lo,
F‘ore igbala Re
Si aya wa gbogbo
L‘ojo Re mimo yi.
AMIN

47 L.M
Oluwa busi Ojo meje, o si ya si mimo. Eks. 20:11
1 f Ojo mefa t‘ise koja
Okan t‘isimi si bere,
Wa okan mi si ‗simi re,
Yo s‘ojo t‘Olorun busi

2 f Olorun, a yo si ‗se Re,


L‘oniruru t‘ogbo t‘o otun;
A fi ‗yin ro anu t‘o lo,
A ni ‗reti s‘eyi ti mbo.

3 Ki ‗ronu at‘ope wa nde,


Bi ebo turari s‘orun,
K‘o le fa inu didun wa
T‘o je teni t‘o mo nikan

4 Ibale aya orun yi,


L‘eri isimi t‘o logo;
To wa fun eniyan mimo,
P Opin aniyan at‘aisan.
AMIN

48 C.M
E yi li ojo ti Oluwa da; awa o ma yo inu wa yo si ma dun ninu Re. OD 118:28
1 f Eyi l‘ojo t‘Oluwa da,
O pe ‗gba na n‘ti Re;
Korun k‘o yo, k‘aye ko yo
K‘iyin yi ‗te na ka.

2 loni O jinde n‘nu oku,


Ijoba satan ‗tu
‗Won mimo tan ‗segun Re ka
Won ns‘oro ‗yanu Re.

3 ff Hosana si Oba t‘a yan


S‘omo mimo Dafid‘,
Mf Oluwa, jo sokale wa
T‘Iwo t‘igbala Re.

4 Abukun l‘Oluwa t‘o wa


N‘ise ore-ofe
T‘o wa l‘oruko Baba Re,
Lati gba ran wa la.

5 ff Hosana ki ohun goro,


L‘orin ijo t‘aye,
Orin t‘oke orun l‘ohun,
Yio dun ju be lo.
AMIN

49 L.M
Nitori Iwo, Oluwa li o ti mu mi yo nipa Ise re. OD 92:4
1 f Didun ni ‗se na, Oba mi,
Lati ma yin Oruko Re,
Lati se ‗fe Re l‘owuro
Lati so oto Re l‘ale.

2 p Didun l‘ojo ‗simi mimo,


Lala ko si fun mi l‘oni,
Okan mi ‗ba le ma korin
Bi ohun duru Dafidi!

3 p Okan mi o yo n‘Oluwa,
Y‘o yin ise at‘oro Re
Ise ore Re ti po to!
Ijinle si ni imo Re.

4 mf Emi o yan ipo ola


‗Gb‘ ore ofe ba we mi nu,
Ti ayo pupo si ba mi
Ayo mimo lat‘oke wa.

5 f ‗Gbana un o ri, un o gbo, un o mo


Ohun gbogbo ti mo ti nfe,
Gbogbo ipa mi y‘o dalu
Lati se ife Re titi.
AMIN

50 7.7.7.7
Nitorina, isimi kan ku fun awon eniyan Olorun. Heb. 4:9
1 mf K‘ojo ‗simi yi to tan,
K‘a to lo f‘ara le le,
Cr Awa wole lese Re,
Di A nkorin iyin si O.

2 mf Fun anu ojo oni,


Fun isimi l‘ona wa,
F ‗Wo nikan l‘a f‘ope fun,
Oluwa at‘Oba wa,
3 p Isin wa ko nilari
Aura wa lu m‘ese,
Sugbon ‗Wo l‘o nfese ji
Or‘-ofe Re to fun wa.

4 mf Je k‘ife Re ma to wa,
B‘a ti rin ‗nu aye yi,
Mp Nigbat‘ajo wa ba pin,
K‘a le simi l‘odo Re.

5 f K‘ojo ‗simi wonyi je


Ibere ayo orun,
B‘a ti nrin ajo wa lo
Si ‗simi ti ko lopin.
AMIN

51 S.M
Yio si dabi imole oro nigbati orun ba la ati ti ko ni kuku. II Sam. 23:4

1 f O jo mole l‘eyi,
Mf Ki ‗mole wa loni,
Cr ‗Wo orun ran s‘okunkun wa,
K‘o si le oru lo.

2 p Ojo ‗simi l‘eyi


Mf S‘agbara wa d‘otun
Di S‘ori aibalo aya wa
Mp Se ‗ri itura Re.

3 p Ojo alafia,
Mf F‘alafia fun wa:
Cr Da iyapa gbogbo duro,
Si mu ija kuro.

4 p Ojo adura ni;


Mf K‘aye sunmo orun;
Cr Gb‘okan wa s‘oke sodo Re,
Si pade wa nihin.

5 f Oba Ojo l‘eyi;


Mf Fun wa ni isoji;
Ff Ji oku okan wa s‘ife;
‗Wo asegun iku.

AMIN

52 S.M
Emi o si bere lowo Baba, oun o si fun Yin li Olutunu miran, ki o le ma ba yin gbe titi laelae. Jn. 14:6
1 f Emi wa ba wa pe,
L‘ojo isimi yi;
Laisi Re awa ko le sin,
A ko le gb‘adura

2 f Asan li orin wa,


Iwasu wa asan,
Ipejopo wa ko l‘ere
Afi b‘O pelu wa.

3 f Ojise Orun nla,


Tani mo je bi Re?
Tikalare wa
Nipa iranse Re.

4 f Wa ko wa lati be,
L‘ohun t‘a ba toro;
Si mu ‗bere wa to jesu
T‘a be l‘oruko Re.

5 mf Nipa ‗ranlowo Re
L‘a n‘ireti anu,
Isin wa ko le sai l‘ere
B‘Iwo ba pelu wa.
AMIN

53 C.M
Mo wa ninu emi li ojo Oluwa. Ifi. 1:10
1 f Je k‘a yin Oluwa ‗simi
Pelu awon mimo,
Ti n f‘ayo at‘orin didun
Lo ‗simi ailopin

2 mf Oluwa, b‘a ti nranti Re


N‘ibukun wa npo si;
Nipa orin iyin l‘a nko
B‘a ti y‘ayo ‗segun

3 Lojo ayo yi l‘Olorun,


Oro ayeraye,
F‘ise nla han, t‘o logo ju
Ti iseda aye

4 f O jinde, eni f‘irora


Di Ra gbogb‘eda pada;
Ise nla ni dida aye,
P Idande ju yi lo.
AMIN

54 C.M
Ranti Ojo isimi, lati ya a simimo. Eks. 20:8
1 f B‘o ti dun to l‘oj‘owo yi,
Ojo t‘adara ju
Ki a pa ‗ronu aye ti,
K ronu nkan t‘orun!

2 mf B‘o ti dun to lati l‘aye


Bebe fun ‗dariji!
K‘a fi igboya omo pe
―Baba ti mbe l‘orun‖

3 Lati gb‘or‘ alafia didun


Lat‘enu ranse Re;
P Lati mu k‘a sokun ese,
K‘a ri ona orun

4 p B‘o ba si je pe o ti wa
Lati le ese lo,
Eni t‘o nwo inu okan,
Y‘o ran or‘ ofe wa

5 f Nje ma wole ojo owo,


Ojo t‘o dara ju,
T‘okan pe lati san eje
Im‘ore fun orun.
AMIN

55 S.M
Ranti ojo isimi, lati ya a simimo. Eks. 20:8

1 f Olorun wa orun,
T‘o fi ojo mefa
Da nkan gbogbo ti mbe laye
Simi n‘ijo keje

2 f O pase k‘a bowo


Fun ojo isimi;
Ibinu Re tobi pupo
S‘awon t‘o rufin yi.
3 Awon baba nla wa,
P Ti ku nin ‗okunkun;
Won je ogbo aborisa
Won ko mo ofin re

4 mf Awa de Oluwa,
Gege bi ase Re;
Leyin ise ojo mefa,
Lati se ife Re.

5 mf Mimo l‘ojo oni,


O ye ki a simi,
K‘a pejo ninu ile Re,
K‘a gbo ‗ro mimo Re.

6 Isimi nla kan ku


F‘awon eniyan Re;
Om‘ Olorun, Alabukun
Mu wa de simi Re!
AMIN

56 8.7.8.7.D
Mo si gbo bi enipe ohun opolopo eniyan ati bi iron omi pupo, ati bi iro ara nlanla, nwipe, Aleluya nitori Oluwa Olorun wa, Olodumare njoba. Ifi 19:6

1 f Gbogb‘ogun orun nro keke,


E Angeli mu harpu won,
Awon mimo nt‘ohun won se,
Lati josin t‘o l‘ogo;
Ojo ‗simi t‘Olorun de
Ojo t‘o l‘ogo julo,
Orun kun fun iho ayo
A! b‘isin won ti dun to.

2 f Jek‘a pelu awon t‘orun,


Yin Olorun Oba wa;
Jek‘a pa ‗le okan wa mo,
K‘a f‘ohun mimo korin
Apere ni ti wa le je
T‘isimi ti won loke
Titi ao fi ri Oluwa
Ti a nsi l‘ojukoju

3 mf K‘o to d‘igba na, e jeki


A ma sin l‘ojo keje,
K‘a f‘aniyan wa s‘apakan
K‘a pe sinu ile Re;
O ti pase k‘a ma se be,
Y‘o bukun ipejo wa,
E je k‘a sin li aisare
Ere re y‘o je tiwa
AMIN

57 C.M
Inu mi dun nigbati won wi fun mi pe, E je ka lo sile Oluwa. OD 122:1

1 f Bi mo ti yo lati gb‘oro
L‘enu awon ore;
Pe, ―Ni Sion‘ni k‘a pe si
K‘a p‘ojo mimo mo‖

2 f Mo f‘onata at‘ekun re;


Ile t‘a se loso,
Ile t‘a ko fun Olorun;
Lati fi anu han

3 S‘agbala ile ayo na,


L‘eya mimo si lo,
Omo Dafid‘wa lor‘ite,
O nda ejo nibe.

4 O gbo iyin at‘igbe wa;


Bi ohun eru re
Mp Ti nya elese sib‘egbe,
A nyo ni wariri

5 K‘ibukun pelu ibe na


Ayo nigbakugba;
K‘a fi ore ati ore,
F‘awon ti nsin nibe

6 Okan mi bebe fun Sion‘


Nigbati emi wa;
F Nibe ni ‗batan at‘ore
At‘Olugbala wa.
AMIN

58 L.M
Awon ne emi o si mu wa si oke mimo Mi, emi o si mu inu won dun, ninu ile Adua mi. Isa. 56:7
1 f Ayo l‘ojo ‗simi fun mi,
At‘agogo at‘iwasu;
P Gbat‘a ba mi n‘nu ‗banuje
Mf Awon l‘o nmu inu mi dun

2 Ayo si ni wakati na
Ti mo lo n‘nu agbala Re;
Lati mo adun adura
Lati gba manna oro Re
3 f Ayo ni idahun ―Amin‖
T‘o gba gbogbo ile na kan,
Lekokan l‘o ndun t‘o nrole,
O nkoja lo sodo Baba

4 B‘aye fe f‘agbara de mi
Mo ise ijo mefa re;
Mf Oluwa, jo, tu ide na,
K‘o so okan mi d‘ominira

AMIN

59 6.6.7.6.7.6.7.6
Ojo keje li ijo isimi Oluwa Olorun Re. Eks. 20:10

1 mf Ose, oso rere,


Iwo ojo simi;
O ye k‘a fi ojo kan
Fun Olorun rere;
B‘ojo mi ba m‘ekun wa,
Iwo n‘oju wa nu;
Iwo ti s‘ojo ayo,
Emi fe dide re

2 f Ose Ose rere,


A ki yo sise loni;
A o fi‘se wa gbogbo
Fun aisimi ola,
Didan l‘oju re ma dan,
‗Wo arewa ojo;
Ojo mi nso ti lala,
Iwo nso ti simi.

3 f Ose, Ose rere


Ago tile nwipe,
F‘eleda re l‘ojo kan,
T‘O fun o n‘ijo mefa;
A o fi ‗se wa sile,
Lati lo sun nibe
Awa ati ore wa;
A o lo sile adua

4 mf Ose, Ose rere,


Wakati re wu mi;
Ojo orun ni ‗wo se;
‗Wo apere orun;
Mp Oluwa, je ki njogun
‗Simi leyin iku;
Ki nle ma sin O titi,
Pelu eniyan Re.
AMIN

60 6.6.6.6.8.8.
Ki eniyan ki o si ma pa ojo isimi mi mo, ki eniyan ki o si b‘owo fun ibi mimo mi; Emi ni Oluwa. Lef. 19:30

1 f Ji, eyin mimo ji,


Ek‘ojo owo yi,
E fi orin iyin
A‘tayo juba Re;
Wa bukun ojo t‘a bukun
Eya isimi ti orun

2 f Ni oro rere yi
L‘Oluwa ji dide,
O fo ‗lekun iku,
O segun ota wa;
O si ngb‘ejo wa ro loke,
O nkore eso ife Re.

3 ff Kabiyesi, Oba!
Hosana ndun loke;
Aye l‘ohun ‗rele;
Si ngba iyin Re ko;
Yiye ‗Od‘aguntan t‘a pa,
Lati wa, lati joba lea
Amin

61 7.7.7.7.
Nibe ni awon igbekun simi po, nwon ko si gbohun amunisin mo. Jobu 3:18
1 mf Imole, Ojo ‗simi,
Je l‘o ku mo wa l‘oju
B‘igbat‘orun iba wo,
Fun ajo onigbagbo

2 mf B‘imole ti nrekoja
Oru t‘aso bo aye;
Gbogbo nkan dake roro,
N‘ipari ojo ‗simi

3 Alafia kun‘aye
Ti Olorun mimo ni,
Apere t‘inu okan
Ti o bo lowo ese

4 Sibe Emi duro ti


Awon t‘o nsin l‘asale,
T‘o gbe okan won s‘oke,
To nsare si ebun na
5 p Jesu je k‘isimi wa
Je ti ayo ninu Re,
Pp Tit‘okan wa y‘o simi,
Nibi ‗simi ailopin

Amin

62 L.M
Ni ijo mefa ni iwo o sise. Eks. 20:9
1 f Ojo isimi Olorun,
Ojo ti o dara julo;
Ti Olorun ti fun wa;
K‘awa k‘o simi ninu re

2 Ijo mefa l‘O fi fun wa,


K‘a fi se ise wa gbogbo;
Sugbon ojo keje yato,
Ojo ‗simi Olorun ni

3 mf K‘a fi ‗se asan wa sile,


Ti awa nse n‘ijo mefa;
Mimo ni ise ti ni,
Ti Olorun Oluwa wa.

4 f A para di nissiyi
Ninu ile Olorun wa;
Jek‘a korin didun si I,
Li owuro ojo oni.

5 Ni kutukutu ‗jo keje


Ni ojo simi mimo
Ff Jek‘a jumo korin didun,
Je k‘a si jumo gbadura.

AMIN

63 S.M
Won nkigbe li ohun rara, wipe, Yio ti pe to Oluwa? Ifi 6:10
1 f Abe a fe ri O,
Ojo ‗simi rere
Gbogbo ose a ma wipe
Iwo o ti pe to?

2 O ko wa pe Kristi
F Jinde ninu oku;
Gbogbo ose a ma wipe,
Iwo o ti po to?

3 O so t‘ajinde wa
Gege bi ti Jesu;
Gbogbo ose a a wipe;
Iwo o ti o pe to?

4 mf Iwo so t‘isimi,
T‘ilu alafia;
T‘ibukun eniyan mimo,
Iwo o ti pe to!
AMIN

64 8.7.8.7
Oluwa si simi nijo k‘eje, Eks. 20:11
1 f Akoko odun at‘osu
Gbogbo won l‘Olorun da;
Ojumo ni fun ise wa,
Oru si ni lati sun

2 O si da ojo isimi;
N‘nu ‗jo meje, O mu ‗kan,
K‘eniyan ba le r‘aye se
Ati sin olorun won

3 L‘ojo mefa ni k‘a sise


B‘o ti ye ni ki a se;
L‘ojo keje je k‘a pejo,
Ni ile Olorun wa

4 L‘ojo na yi a ngbadura,
A nkorin didun si I
A si nyin Olorun l‘ogo
T‘o ju ohun gbogbo lo

5 Nissiyi korin iyin,


T‘Olorun Oluwa wa;
Ff Korin didun, Korin soke,
Ni yiyin Oluwa wa.

AMN

ORIN IYIN
65 S.M
E dide, ki e fi iyin fun Oluwa Olorun yin lae ati laelae; ibukun si ni fun Oruko Re li o li ogo ti oga ju gbogbo ibukun ati yin lo. Neh. 9:5

1 mf Dide, yin Oluwa,


Eyin ayanfe Re,
Cr F‘okan, emi at‘ohun re
F F‘ibukun f‘Olorun

2 mf B‘O tile ga ju ‗yin


Ati ibukun lo,
Cr Tani k‘yo beru oko Re,
F Ti ki yo si gbega

3 mf Ina ‗mole aye


Lat‘odo Olorun
F To ete wa, m‘okan soji,
Di M‘ero wa lo s‘orun

4 cr Olorun, l‘agbara,
F Orin, igbala wa;
Ff Ki gbogb‘ agbara wa kede
Ife Re n‘nu Kristi

5 f Dide, yin Oluwa,


Juba Olorun re;
Yin Oruko Re t‘ologo
Lati isiyi lo.
AMIN

66. 12.10.12.10. D
E fi iyin fun Oluwa. OD. 106:1

1 f Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa,


Ki aye k‘okiki ife Re nla,
Fi iyin fun! Eyin Angeli o‘logo,
F‘ola at‘ogo fun oruko Re
Mf B‘Olus‘agutan, Jesu y‘o to
Omo Re,
L‘apa Re l‘o ngbe won le l‘ojojo;
Eyin eniyan mimo ti ngb‘oke Sion;
f Fi iyin fun pelu orin ayo

2 Fi iyin fun, Jesu Olurapda wa,


Mp Fun wa, O t‘eje Re sile, O ku,
Cr On ni apata, ati reti‘gbala wa,
F Yin Jesu ti a kan m‘agbalebu;
Mf Olugbala t‘O f‘ara da irora nla,
Di Ti a fi ade egun de l‘ori,
P Eniti a pa nitori awa eda
Mf Oba ogo njoba titi laelae

3 f Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa


Ki ariwo iyin gba orun kan,
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se l‘Oba gbogb‘ eyin alagbara;
A segun iku: fi ayo royin na ka,
Mp Isegun re ha da, isa oku?
Cr Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
F T‘ori O l‘agbara lati gbala
AMIN
67 10.11.10.11 & Ref
Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD 89:1

1 f Em‘o yin Oluwa fun ife Re,


A we mi nin ‗eje Olurapada,
Mf Eje na t‘o nsan nib‘agbelebu,
A we mi nin‘eje Olurapada,
F‘ Ogo, Ogo fun Od‘agutan
O gba mi l‘owo ese mo si di mimo,
Ff Ogo, Ogo, Ogo, f‘Od‘agutan,
A we mi nin‘eje Olurapada

2 f Ore-Ofe mu mi sunm‘odo Re,


A we mi nin‘eje Olurapada,
Em‘o korin soke, aye y‘o gbo,
A we mi nin‘eje Olurapada

3 Alafia wo l‘o to yi l‘okan mi?


A we mi nin‘eje Olurapada;
Ayo mimo na ko se f‘enu so,
A we mi nin‘eje Lurapada,

4 ff Emi o ma gb‘ohun iyin s‘oke,


A we mi nin‘eje Olurapada,
Okan mi y‘o ma korin lojojo
A we mi nin‘eje Olurapada.
AMIN

68 11.11.11.11 & Ref


E korin titun si Oluwa; nitori O ti se ohun iyanu. OD 98:1
1 f Eyin Oba Ogo, On ni Olorun,
Yin I fun ‗se ‗yanu ti O ti fi han,
O wa pel‘awon ero mimo l‘ona
O si je imole won l‘osan l‘oru
Eyin angeli didan lu duru wura,
Ki gbogbo nyin juba t‘e nwo oju Re,
Ni gbogbo ‗joba Re, b‘aye ti nyi lo,
Ise Re y‘o ma yin,
Ise Re y‘o ma yin,
Fi ibukun fun Oluwa okan mi

2 E yin fun ‗rapada, ti gbogbo okan,


E yin fun orisun imularapa
Fun inu rere ati itoju Re,
Fun ‗daniloju pe O ngbo adura,

3 E yin fun idanwo, bi okun ife,


T‘o nso wa po mo awon ohun orun,
Fun ‗gbogbo ti nsegun ‗reti ti ki sa
Fun ile Ogo t‘O ti pese fun wa.

Amin

69 L.M & Ref


Oruko Oluwa ni ki ayin. OD. 113:3
1 f B‘oruko Jesu ti dun to,
Ogo ni fun Oruko Re
O tan banuje at‘ogbe
Ogo ni fun Oruko Re
Ogo f‘oko Re, Ogo f‘oko Re,
Ogo f‘oruko Oluwa
Ogo f‘oko Re, Ogo f‘oko Re,
Ogo f‘oruko Oluwa

2 O wo okan to gb‘ogbe san


Ogo ni fun Oruko Re
Onje ni f‘okan t‘ebi npa,
Ogo ni fun Oruko Re

3 O tan aniyan elese,


Ogo ni fun oruko Re
O fun alare ni simi
Ogo ni fun oruko Re

4 Nje un o royin na f‘elese,


Ogo ni fun Oruko Re
Pe mo ti ri Olugbala
Ogo ni fun Oruko Re.
AMIN

70 6.6.8.4. D
E yin oruko Oluwa Olorun yin, eniti o fi iyanu ba yin lo. Joe 2:26
1 f Yin Olorun Abra‘am,
Ti O njoba l‘oke
Eni t‘O ti wa titi lae
Olorun ‗fe
―Jehofa nla Emi‖
Gbogbo eda jewo,
Mo fi ‗bukun Re
Titi laelae

2 mf Yin Olorun Abra‘am,


Nip‘ase Eni ti
Mmo dide, mo si wa ‗tunu
Lowo ‗tun Re;
Mo ko aye sile;
Ogbon at‘ola re;
On nikan si ni ipin m
At‘asa mi
3 f On na ti se ‗leri;
Mo gbekele eyi,
U n I fi iye idi goke
Lo si orun
Un o ma wo oju Re
Un o si yin ipa Re,
Un o korin ‗yanu to‘or‘ofe
Titi laelae

4 di B‘agbara eda pin,


T‘aye at‘esu nde,
Un o d‘ojuko ona kenan‘
Nipa ‗se Re
Un o re odo koja
Bi Jesu wa lokan
Un o koja n‘nu igbo didi
Lo s‘ona mi.

5 mf Oba Oke orun


Olor‘Angeli nke
P Wipe ―Mimo, Mimo, Mimo‖
Oba titi
Cr En ‗ti ki yi pada,
F Ti y‘o si wa laelae
Ff Jehofa Baba, ―Emi ni‖
Awa yin O

6 f Gbogbo ‗gbe asegun


Yin Olorun loke,
Baba, Omo at,Emi, ni
Won nke titi
Ff Yin Olorun Abra‘am!
Un o ba won korin na,
Tire l‘agbara at‘ola
Pelu iyin.
AMIN

71 7.7.7.7
Nitori ti anu Re duro laelae. OD 136:1
1 mf E je k‘a f‘inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju

2 On nipa agbara Re
F‘imole s‘aye titun
Anu Re, O wa titi,
Lododo dajudaju,
3 O mbo gbogb‘eda ‗laye,
O npese fun aini won,
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju

4 cr O bukun ayanfe Re
Li agiju iparun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajadaju

5 f E je k‘a f‘inu didun


Yin Oluwa Olore,
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju
Amin
72 L.M
E ho iho ayo si Oluwa, eniyan ile gbogbo. OD 100:1

1 f Niwaju ite Jehofa,


E f‘ayo sin, Orin‘ede
Mo p‘Oluwa, on nikan ni,
O le da, O si le parun

2 mp Ipa Re, laisi ranwo wa,


F‘amo da wa ni eniyan;
P Nigba t‘a sako b‘aguntan
Cr O tun a mu si agbo Re,

3 f A o f‘orin Sunmo ‗le Re,


Lohun giga l‘ao korin;
Ile, ‗legbarun ahon re,
Y‘o fiyin kun agbala Re

4 Ase Re gboro k‘agbaye,


Ife Re po b‘ayeraye;
Oto Re y‘o duro laelae
Gbat‘odun o dekun ‗yipo
AMIN

73 C.M
Emi o ma fi ibukun fun Oluwa nigbagbogbo OD 34:1

1 mf N‘nu gbogbo ayida aye


Ayo on wahala;
Cr Iyin Olorun ni y‘o ma
Wa l‘enu mi titi

2 f Gbe Oluwa ga pelu mi,


Ba mi gb‘oko Re ga:
Mp N‘nu wahala, ‗gba mo ke pe
F O si yo mi kuro

3 Ogun Olorun wa yika


Ibugbe Oloto;
Eniti o ba gbekele,
Yio ri igbala

4 mf Sa dan ife Re wo lekan


‗Gba na ‗wo o mo pe,
Awon t‘o di oro Re mu
Nikan l‘eni ‗bukun

5 mf E beru Re, eyin mimo,


Eru miran ko si;
Cr Sa je ki ‗sin Re j‘ayo yin
F On y‘o ma tojun yin
AMIN

74 C.M
Kili emi o fi fun Oluwa, nitori gbogbo ore Re simi? OD 116:12

1 f Fun anu t‘o po b‘iyanrin,


Ti mo ngbo lojumo;
Lat‘odo Jesu Oluwa;
Ki l‘emi o fi fun?

2 p Kini un o fi fun Oluwa,


Lat‘inu Okan mi?
Ese ti ba gbogbo re je,
Ko tile jamo nkan

3 cr Eyi l‘ohun t‘emi o se


F‘ohun t‘O se fun mi:
Emi o mu ago igbala,
Un o kepe Olorun

4 mf Eyi l‘ope ti mo le da,


Emi osi, are;
Em‘o ma soro ebun Re,
Un o si ma bere si.

5 Emi ko le sin boti to,


Nko n‘ise kan to pe,
F Sugbon em‘o sogo yi pe,
Gbese ope mi po
AMIN

75 C.M
Emi mi si yo si Oorun Olugbala mi. Lk. 1:47
1 f Emi ‗ba n‘egberun ahon,
Fun ‗yin Olugbala,
Ogo Olorun Oba mi,
Isegun ore Re.

2 p Jesu t‘o seru wa d‘ayo


T‘o mu banuje tan
Orin ni l‘eti elese
Cr iey at‘ilera

3 mf O segun agbara ese


O da onde sile,
Di Eje Re le w‘eleri mo,
P Eje Re seun fun mi

4 cr O soro, oku gb‘ohun Re,


O gba emi titun,
Onirobinuje y‘ayo,
Otosi si gbagbo

5 f Odi, e korin iyin re,


Aditi, gbohun Re;
Afoju, Olugbala de,
Ayaro, fo f‘ayo

6 Baba mi at‘Olorun mi,


Fun mi ni ‗ranwo Re;
Ff Ki nle ro ka gbogbo aye,
Ola oruko Re.
AMIN

76 610.10.11.11
Oluwa, Olorun mi, Iwo tobi jojo. OD. 104:1

1 f E wole f‘Oba, Ologo, julo,


E korin ipa ati ife Re;
Alabo wa ni at‘Eni igbani,
O ngbe ‗nu ogo, Eleru ni iyin

2 E so t‘ipa Re, e so t‘ore Re;


‗Mole l‘aso Re, gobi Re orun,
Cr Ara ti nsan ni keke ‗binu Re je,
Ipa ona Re ni a ko si le mo

3 m Aye yi pelu ekun ‗yanu Re


Olorun agbara Re l‘o da won,
O fi idi re mule, ko si le yi;
O si f‘okun se aso igunwa Re

4 cr Enu ha le so ti itoju Re?


Ninu afefe ninu imole;
Di Itoju Re wa nin‘odo ti o nsan
P O si wa ninu iri ati ojo

5 mp Awa erupe aw‘alailera


‗Wo l‘a gbekele, O ki o da ni
Cr Anu Re rorun o si le de opin
F Eleda, Alabo, Olugbala wa

6 ff ‗Wo Alagbara Onife jule


B‘awon Angeli ti nyin O loke
Di Be ‗awa eda Re, niwon t‘a le se
Cr A o ma juba Re, a o ma yin O
AMIN

77 C.M
Oun li Oluwa awon luwa ati Oba awon oba. Ifi. 17:14

1 f Gbogbo aye, gbe Jesu ga,


Di Angel‘, e wole fun;
Cr E mu ade Oba Re wa,
F Se l‘Oba awon Oba

2 mf E se l‘Oba ein Martyr,


Ti npe ni pepe Re;
Cr Gbe gbongbo igi, Jese ga
F Se L‘Oba awon oba

3 mf Eyin iru omo Israeli‘,


Ti a ti rapada;
Cr E ki Eni t‘o gba yin la,
F Se l‘Oba awon oba.

4 p Gbogbo eniyan elese


Ranti ‗banuje yin;
Cr E ti ‗kogun yin s‘ese Re,
F Se l‘Oba awon oba

5 ff Ki gbogbo orile ede,


Ni gbogbo agbaye,
Ki won ki, ‗‖kabiyesile‖
Se l‘Oba awon oba

6 mf A ba le pel‘awon t‘orun
Lati ma juba Re;
Cr K‘a bale jo jumo korin,
Ff Se l‘Oba awon oba
AMIN

78 8.7.8.7.8.7
Mo gbohun nla kan ti opolopo eniyan Lorun, wipe Aleluya. Ifi 19:1

1 f Aleluya! Orin t‘o dun,


Ohun ayo ti ki ku;
Aleluya! Orin didun,
A‘won t‘o wa lorun fe;
N‘ile ti Olorun mi ngbe
Ni won nko tosantoru

2 Aleluya! Ijo t‘orun,


E le korin ayo na
Aleluya! Orin ‗Segun
Ye awon ta rapada
Awa ero at‘aljo
Di Iyin wa ko nilari

3 mp Aleluya! Orin ayo


Ko ye wa nigba gbogbo
Aleluya! Ohun aro,
Da mo orin ayo wa;
P Gba t‘awa laye osi yi
Di A ni gbawe f‘ese wa

4 cr Iyin dapo m‘adura wa


Gbo tiwa, metalokan!
Mu wa de ‗waju Re layo
K‘ar‘Od‘aguntan t‘apa
F K‘a le ma ko Aleluya
Nibe lae ati laelae
AMIN

79 8.7.8.7.4.7
Fi ibukun fun Oluwa, Iwo okan mi. OD. 103:1

1 f Okan mi yin Oba orun,


Mu Ore wa sode Re,
Mp ‗Wo ta wosan, t‘a dariji
Cr Tal‘aba ha yin bi Re?
Yin Oluwa, Yin Oluwa
F Yin Oba Ainipekun

2 mf Yin fun anu t‘o fi han


F‘awon Baba ‗nu ponju;
Yin l‘Okan na ni titi
O lora lati binu
F Yin Oluwa, Yin Oluwa,
Ologo n‘nu otito

3 p Bi Baba ni O ntoju wa
O si mo ailera wa;
Jeje l‘o ngbe wa lapa Re
O gba wa lowo ota,
Yin Oluwa, Yin Oluwa
Anu Re, yi aye ka

4 ff Angel, e jumo ba wa bo
Eyin nri lojukoju
Orun, Osupa, e wole
Ati gbogbo agbaye
E ba wa yin, E ba wa yin
Olorun Olotito.
AMIN

80 L.M
Emi o so ti iseun ife Oluwa. Isa. 63:7

1 f Ji, Okan mi, dide l‘ayo,


Korin iyin Olugbala,
Ola Re bere orin mi;
P ‗Seun ife Re ti po to!

2 mf O ri, mo segbe n‘isubu,


Sibe O fe mi l‘a fe tan
O yo mi ninu osi mi;
P ‗Seun ‗fe Re ti tobi to!

3 mf Ogun ota dide simi,


Aye at‘esu ndena mi,
On mu mila gbogbo Re ja
‗Sun ‗fe Re ti n‘ipa to!

4 f ‗gba ‗yonu de b‘awosanma


T‘o su dudu t‘o nsan ara
O duro ti mi larin re;
‗Seun ‗fe Re ti dara to!

5 ‗Gba gbogbo l‘okan ese mi,


Nfe ya l‘eyin Oluwa mi
Sugbon bi mo ti ngbagbe Re
Iseun Ife Re ki ye
AMIN

81 7.7.8.7.D
Ninu iponju li awa o de Ijoba orun. Ise A. 14:22

1 f Olorin ijo t‘orun


L‘ayo l‘a wole fun O,
Ki O to de, Ijo t‘aye;
Y‘o ma korin bi t‘orun‘
Ff A gbe okan wa s‘oke
Ni ‗reti t‘o ni ‗bukun,
Awa kigbe, awa f‘iyin
F‘Olorun igbala w

2 ff ‗Gbat‘ awa ninu ‗ponju


T‘ a nkoja ninu ina
Cr Orin ife l‘awa o ko
Ti o nmu wa sun mo O;
F Awa sa pe, a si yo
Ninu ojurere Re;
Ff Ife t‘o so wa di Tire,
Y‘o se wa ni Tire lae

3 p Iwo mu awon eniyan Re;


Koja isan idanwo,
cr A ki o beru wahala,
Tori O wa nitosi
mf Aye, ese, at‘Esu.
Kojuja si wa lasan
f L‘agbara Re a o segun
A o si ko orin Mose.

4 mf Awa figbagbo r‘ogo,


Ti o tun nfe fi wa si;
cr A kegan aye nitori
Ere nla iwaju wa
p Bi 0 ba si ka wa ye
Awa pelu Stefen t‘o sun
F Y‘o ri O bi O ti duro
Lati pe wa lo s‘orun.

Amin.

82 L.M.
Efi ayo sin Oluwa OD. 100:2.

1 f Gbogbo eyin ti ngbe aye


E f ayo korin s‘Oluwa;
F‘iberu sin, e yin l‘ogo
E wa s‘odo Re, k‘e si yo.

2 Oluwa, On ni Qlorun,
Laisi ‘ranwo wa O da wa;
Agbo Re ni wa, O mbo wa;
O si fi wa s‘agutan Re.

3 Nje, f‘iyin wo ile Re wa


F‘ayo sunmo agbala Re;
Yin, k‘e bukun oruko Re,
‘Tori o ye be lati se.
4 Ese! rere l‘Olorun wa,
Anu Re o wa titi lae,
Oto Re ko fi ‘gbakan ye,
O duro lat‘ irandiran.
Amin.

83
8.8.6.
Emi o Soro iyin olanla Re
ti o logo, ati ti ise iyanu Re. OD. 145:5.

1 mf S i O Olutunu Orun
Fun ore at‘agbara Re,
F A nko, Aleluya.

2 Si O, ife enit‘O wa
Ninu Majemu Olorun
A nko, Aleluya.

3 Si O, agbara Eni ti
O nwe ni mo, t‘o nwo ni san
A nko, Aleluya.

4 Si O, Oluko at‘ore.
Amona wa toto d‘opin,
A nko, Aleluya.

5 mf Si O, Eniti Kristi ran,


F Ade on gbogbo ebun Re,
ff A nko, Aleluya.
Amin.

84
11.12.12.10.
Won ko simi li osan ati li oru wipe,
Mimo, Mimo, Mimo,
Oluwa Olorun Olodumare. Ifi. 4:8.

1 p M imo, Mimo, Mimo Olodumare


mf Ni kutukutu n‘Iwo O gbo orin wa;
p Mimo, Mimo, Mimo! Oniyonujulo,
f Ologo meta, lae Olubukun.

2 mf Mimo, Mimo, Mimo! awon t‘orun nyin


Won nfi ade wura won le ‗le yi ‗te ka
cr Kerubim, Serafim nwole niwaju Re
f.di Wo t‘o ti wa, t‘O si wa titi lae.

3 p Mimo, Mimo, Mimo, b‘okunkun pa o mo


Bi oju elese ko le ri ogo Re
mf Iwo nikan l‘O mo, ko tun s‘elomiran
Pipe ‘nu agbara ati n‘ife

4 f Mimo, Mimo, Mimo! Olodumare


ff Gbogbo ise Re n‘ile l‘oke l‘o nyin O
f.cr Mimo, Mimo, Mimo! Oniyonu julo
ff Ologo meta lae Olubukun! Amin.

85 6.6.4.6.6.6.4.
Tani ki yio beru, Oluwa ti ki yio si fi
ogo fun oruko Re?
Nitoripe iwo nikan soso ni Mimo. Ifi. 15:4.

1 f Baba oke orun


T‘imole at‘ ife
Eni ‘gbani
‘MOLE t‘a ko le wo
Ife t‘a ko le so
IWO Oba airi
Awa yin O.

2 Kristi Omo laelae


‘WO l‘o di eniyan
Olugbala
Eni giga julo,
Olorun Imole
Ai da at‘ailopin
A ke pe O.

3 f Iwo Emi Mimo,


T‘ina Pentikosi Re
Ntan titi lae.
Ma sai tu wa ninu
p L‘aye aginju yi
cr ‘Wo l‘a fe, ‘Wo la nyin
A juba Re.

4 f Angel e lu duru,
K‘orin t‘awa, ti nyin
p Jumo dalu;
Ogo fun Olorun
ff Metalokan soso;
A yin O tit‘ aye
Ainipekun.
Amin.

86 7.7.7.5.

Awon eni-irapada Oluwa yio pada,


WON o si wa si Sioni ti awon ti orin;
ikanu ati ofo yio fo LO. Isa. 51:11.

1 f Olorun Metalokan,
Oba ile at‘okun,
Gbo ti wa bi a ti nko
Orin iyin Re.

2 f ‘Wo imole l‘owuro


Tan ‘mol? Re yi wa ka
Je ki ebun rere Re
p M‘aya wa bale.

3 F ‘WO ‘mole ni gb‘orun WO


K‘a ri idariji gba
Ki alafia Orun
p F‘itura fun wa.

4 f Olorun Metalokan!
Isin wa l‘aye ko to!
A nreti lati dapo
Mo awon t‘orun
Amin.

87 6.6.6.6.8.8.
E fi iyin fun Oluwa. OD. 146:1.

1 mf A Fiyin ailopin
Fun Olorun Baba,
Fun ore aye wa
At‘ireti t‘orun,
O ran Qmo Re ayanfe
p Lati ku fun ese aye.

2 f A fiyin ailopin
Fun Olorun Omo
P T‘o feje Re ra wa,
Kuro ninu egbe,
Nisiyi, O wa, O njoba
O nri eso irora Re

3 f A f‘iyin ailopin
Fun Qlorun Emi,
Eni f agbara Re
SO elese d‘aye;
O pari ise igbala
O si fayo Orun k‘okan.

4 f A f‘ola ailopin
Fun Olodumare,
‘WO Ologo meta
Sugbon Qkan soso,
B‘O ti ju imo wa lo ni,
ff A o ma figbagbo yin O,
Amin

88 7.7.7.7.
Eniti o nfi onje fun eda gbogbo:
nitori anu Re duro laelae.
OD. 136:25.

1 f Yin Qlorun Oba wa,


E gbe ohun iyin ga,
Anu Re, o wa titi;
L‘ododo dajudaju.

2 mf Yin Enit‘o da orun


Ti o nran lojojumo,
F Anu Re, o wa titi;
L‘ododo dajudaju.

3 mp Ati osupa l‘oru,


Tio tan ‘mole jeje,
F Anu Re,owa titi
L‘ododo dajudaju.

4 mf Yin Enit‘om‘ojo ro,


T‘o mu irugbin dagba,
F Anu Re, o wa titi:
L‘ododo dajudaju.

5 mf Enit‘ o pase fun ‗le


Lati mu eso po si;
F Anu Re, o wa titi;
L‘ododo dajudaju.

6 f Yin fun ikore oko,


O mu ki aka wa kun,
Anu Re, o watiti,
L‘ododo dajudaju.

7 mp Yin f onje t‘o ju yi lo,


Eri ‘bukun ailopin
F Anu Re, o wa titi;
L‘ododo dajudaju.

8 un Ogo f Qba olore


Ki gbogbo eda gberin,
Ogo fun Baba, Omo
At‘Emi: Metalokan.
Amin.
89
6.7.6.7.6.6.6.6.
Olorun yi, Olorun wa ni lae ati laelae. OD. 48:14.

1 f A f‘ope f‘Olorun,
L‘okan ati l‘ohun wa.
Eni s‘ohun ‘yanu,
N‘nu eni t‘araye nyo;
mf ‘Gbat‘a wa L‘om‘owo
On na l‘ontoju wa
0 si nf‘ ebun ife
Se 'toju wa sibe.

2 mf Qba Onib‘ore
Ma fi wa sile laelae,
Ayo ti ko l‘opin
On ‘bukun y‘o je ti wa
Pa wa mo n‘nu ore
To wa, gb‘a ba damu;
Yo wa ninu ibi
L‘aye ati l‘orun.

3 un K‘a fiyin on ope,


ff I‘Olorun, Baba, Omo,
Ati Emi mimo;
Ti Oga julo lorun,
Olorun kan laelae,
Amin
90 C.M

Emi o si fi Ota sarin iwo ati obirin na,


ati sarin iru-Omo re ati iru-Omo re.
On o foo li ori, iwo yio si pa a ni gigise
Gen. 3:15.

1 f Iyin f Eni mimo julo


L‘oke ati ni ‗le;
Qro Re gbogbo je ‘yanu,
Gbogb‘ ona Re daju.

2 mf Ogbon Olorun ti po to
p ‘Gbat‘ eniyan subu;
cr Adam‘ keji wa s‘oju ‘ja .
f Ati lati gbala.

3 mf Ogbon ife! p‘eran ara


p T‘o gbe Adam‘ subu
cr Tun b‘ota ja ija otun
f K‘o ja, k‘o si s‘egun.

4 mf Ati p‘ebun t‘o j‘or-ofe


So ara di otun
p Olorun papa tikare
J‘Olorun ninu wa.

5 mf Ife ‘yanu! ti Eni ti


O pa ota eniyan
Ninu awo awa eniyan
Je irora f‘eniyan.

6 p Nikoko, ninu ogba ni


Ati l‘ori igi
cr T‘o si ko wa lati jiya
p T‘o ko wa lati ku.

7 f Iyin f‘Eni mimo julo


L‘oke ati nile
Oro Re gbogbo je ‘yanu
Gbogb‘ ona Re daju.
Amin

91 8.7.8.7.4.7.
Jesu Kristi, eleri Olooto,
Akobi ninu awon oku. Ifi. 1:5.

1 f Oluwa gunwa lori‘te


mf Akobi awon t‘o sun
On nikan l‘Onigbeja wa
To ngbe wa leke ota
cr Aleluya, Aleluya
f Jesu li Onje Iye.

2 mf Awa njuba, awa nsape;


F Kabiyesi Oba wa,
mf Busi igbagbo wa loni
K‘a le tubo mo O si,
F Aleluya, Aleluya
Iwo njoba larin wa.

3 mp Bi a ko tile le ri O
Bit‘awon ti igbani,
cr Awa at‘awon Angeli
Nyin iru-omo Jese.
Aleluya, Aleluya,
TEWO gba ijosin wa.

4 Od‘agutan t‘a fi rubo


Ti s‘etutu f‘ese wa
Ko tun si ebo miran mo
Eje Re ti to fun wa.
Aleluya, Aleluya,
Eje na lo nwe wa mo.

5 O nfi onje iye bo wa


Manna didun lat‘orun
K‘orun at‘aye korin na
Orin ‘yin s‘Od‘agutan.
Aleluya, Aleluya,
O jinde, O si goke.
Amin.

92 8.6.8.6.7.7.7.4. and Ref.


Je ki gbogbo eniyan ki o yin O.
OD. 67:3.

1 f Gbe Oluwa ga pelu mi


Eyin eniyan Re
Ki gbogbo eda alaye
Ma yo l‘oruko Re
Fun ife ti 0 nfihan
Fun isimi l‘okan wa
Fun igbala kikun Re,
Tire l‘ope

Ki gbogbo wa f ope fun


Ki gbogbo wa fope fun
Ki gbogbo wa yin oruko
Oluwa wa
Titi laelae, ani, titi laelae
Ki gbogbo wa f‘ope fun
Ki gbogbo wa f‘ope fun
Ki gbogbo wa yin oruko Oluwa
Titi laelae.

2 Eyin fun iwa-mimo Re,


Fun ore-ofe Re,
Korin iyin fun eje Re
To fi ra wa pada
Ife lo fi wa wa ri
Ninu ira ese wa
O f‘ona iye han wa
E fope fun.

3 Emi ‘ba l‘egberun ahon,


Nko le royin na tan;
Ife Re si mi po jojo,
Ago ‘bukun mi nkun,
Ore-ofe ti ki ye,
Alafia bi odo
Lat‘ odo Olubukun;
E fope fun.
Amin.

93 11.11.11.11. & Ref.


E fi ogo fun Oluwa. OD. 29:2.
1 f ' O go ni f‘Oluwa to se ohun nla
Ife lo mu k‘O fun wa ni OmO Re,
Enit‘O f‘emi Re le ‗le f‘ese wa
To si silekun iye sile fun wa.
Ff Yin Oluwa, Yin Oluwa,
F‘ iyin fun Oluwa,
ff Yin Oluwa, Yin Oluwa,
E YO niwaju Re,
Ka to Baba wa LO l‘Oruko Jesu,
Je k‘ a JO f‘ogo fun Onise-‘yanu.

2 f Irapada kikun ti eje Re ra


F‘enikeni t‘o gba ileri Re gbo,
Enit‘o buruju b‘o ba le gbagbo,
Lojukanna y‘o ri idariji gba.

3 f O s‘ohun nla fun wa, O da wa l‘ola


Ayo wa di kikun ninu Omo Re
Ogo ati ewa irapada yi
Y‘o ya wa lenu ‗gbat‘ a ba ri Jesu
Amin.

94 D.S.M.
Li ori Re re li ade pupo wa.
Ifi. 19:12.
1 f E de l‘ade pupo
Od‘agutan Baba;
Gbo bi orin orun ti bo
Orin gbogbo mole:
Ji, okan mi korin
T‘Eni to ku fun O,
Se l‘Oba re togajulo
Titi ati laelae.

2 f S‘Omo Wundia l‘Qba!


Om‘Olorun t‘a bi
Ti ade Re n mi legbe fun
Ami isegun R?;
Silo ti a so tele,
Eka igi Jese,
Olus‘agutan agbo Re
Omo ti Betlehem'.
3 f S‘Oluwa ye l‘Oba
To segun iboji
To si ji dide ni ‗SEGUN
F‘awon to wa ‗gbala
Orin ogo la nko yi
T‘Eni to ku, to ji
O ku ko ba mu iye wa
O ye ki ‗ku le ku

4 f Se l'Oba alafia!
‗Joba Re k‘ yo lopin;
Nibiti ogun wole fun
Ife titi iyin
Ati yika ese
Re ti a kan niso
Egberun ede ni ‘dapo
Yo korin didun si.

5 f Oluwa loba
Ti O gunwa loke
Se l‘Oba ti a fun l‘oko
lyanu ‘ti Ife;
E de l‘ade pupo,
Awon ti ngbe aye
Ati gbogbo oba aye.
N‘ tor‘On l‘Oba eda.

6 f Se l‘Oba gbogbo‘gba,
Qba ayeraye,
Eleda gbogbo irawo,
Agba ‘yanu leyi:
Olurapada wa!
To ku nitori mi;
Iyin Re ki yo lopin
lae Laelae ati laelae.
Amin.

95 14.14.4.7.8.
Nitori ninu Re li a ti da ohun gbogbo,
ohun ti mbe li orun ati ohun ti mbe li aye
Kol. 1:16.

1 f Y in Oluwa Olodumare,
Oba Eleda
Yin Okan mi to r‘On ni ‘lera
ati ‘gbala re
Arakunrin,
Arabinrin sunmo ‘hin
F‘ayo at‘orin juba Re
2 f Yin Oluwa, Eni t‘Ojoba
lor‘ ohun gbogbo
To dabobo, to si gbe o ro
labe iye Re
O ha ri pe?
Gbogb‘ ohun toto lo se
B‘O ti lana n‘ipase.

3 f Yin Oluwa to mbukun ‘se re


to si ngbeja re;
L‘otito ire ati anu Re nto o leyin
‘Gbana ronu
Ohun t‘Oluwa le se
Eni to fe o, t‘O yan o.

4 f Yin Oluwa! Ki gbogb‘ eya


ara mi juba Re
Ki gbogbo ohun t‘o l‘emi
wa pelu iyin Re.
Je ki iro
Amin dun jake jado,
Layo lao juba Re titi.
Amin.

96 8.7.8.7.4.7.
Oluwa jOba: O joko larin a won Kerubu. OD. 99:1.

1 mp O lorun Oluwa l‘Oba


cr Aye mbe niwaju Re:
Nibi t‘awon angel‘ nsin I,
L‘O gunwa ni ite Re
Eni mimo;
Obangiji, On l‘Oba.

2 f Oba ogo li Olorun,


Sion, royin Re k‘aye;
Isra-eli ti igbani,
Kede itan oto Re:
Eni mimo,
Mimo li oruko Re.

3 Li atijo, ni ‘gba ewu


T‘awon ojise Re be,
O gbo ‘gbe awon eniyan Re,
N‘nu eru Won, O dahun,
Eni mimo;
Won ri n‘tosi‘gba won p‘E.

4 mf Awon l‘afun 1‘ofin mimo


Lat‘ inu awosanma;
Ilana mimo ti won ru,
p Mu ki O binu si won:
Eni mimo;
Won kanu fun ese won.

5 cr Sugbon Baba won fiji won,


‘Gba won tun saferi Re
mf O mura tan lati gba won
f O f‘ife gba won pada:
Eni mimo;
mf Awa na nw‘ or‘-ofe Re.

6 Baba wa n‘iyonu n‘nu Krist‘,


Y‘o mu ileri e? se:
F Wa, k‘a gbe ga, gbogb‘alaye;
E wa soke mimo Re!
Eni mimo;
E sin loke mimo Re
Amin.

97 C.M.
Emi o ma korin anu Oluwa laelae. OD. 89:1.

1 mf Olorun ‘gbat‘ okan mi wo


Gbogbo anu Re nla,
Iran na mu ki emi kun
Fun ‘yanu, ‘fe iyin.
2 f Itoju Re fi aimoye
Itunu f‘okan mi,
K‘okan omode mi to mo
‘Bi ti ‘re na ti nsan.

3 mf L‘ona yiyo odomode


Mo sare laiwoye;
'OWO anu Re l‘o to mi
Titi mo fi dagba.

4 Larin ewu, ati iku,


O nto isise mi;
Ati n‘nu ikekun ese
T‘o li eru julo

5 mp Nigbat‘ aisan je mi l‘ara,


‘Wo tun fun mi lokun
‘Wo f or‘-ofe mu mi soji
Gbat‘ ese bori mi.

6 mf Fun egbegberun ebun Re,


Mo nsope lojojo;
Ati f‘okan t‘o m‘ ore Re,
Ti ngba won pel ‘ ayo.

7 Ni gbogbo igba aye mi


Un o lepa ore Re;
di Leyin iku, l‘aye ti mbo,
cr Un o tun ore Re SO.

8 f U n ma korin ope si O,
Titi ayeraye;
ff Sugbon ayeraye ko to
So gbogbo iyin Re!
Amin

98 C.M.
Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore Re si mi. OD. 116:12.
1 mf K ini un o fun Olorun mi
Fun gbogbo anu Re?
Un o gba ebun Re, un o si fi
Irele bere si.

2 cr Ago or‘-ofe igbala


L‘emi o f‘ope gba,
Un o feyinti iieri Re,
Uno si wa f‘ogo Re.
3 mf Loju awon eniyan Re
Ni un o san eje mi,
Uno f‘ara mi on ini mi
Fi josin f‘Olorun.
4 mp Baba, gbogb‘ ohun ti mo ni
‘Wo l‘o fijinki mi;
Mo je omp Re laye yi,
‘Wo si ra mi pada.

5 Owo Re l‘o da mi, lo si


Da mi n‘de n‘nu ese;
Anu Re t‘o tu ide mi
Si ti de mi mo O

6 f Olorun Olodumare mi,


Uno ma kokiki Re,
Enu y‘o ru ebo iyin,
Un o kepe oko Re.

7 ff E f‘iyin f‘OIorun ife


T'o f‘ese mi ji mi,
Titi ao pelu ‘jo toke
Ko orin ti orun.
Amin.

99. 11.11.11.11.
Fun Oba ayeraye, aidibaje, airi,
Olorun kansoso ni Ola ati ogo
wa fun lae ati laelae. I Tim. 1:17.

1 mf Oba aiku, airi, orisun ogbon


To wa n‘nu imole t‘oju kole wo,
Olubukun julo, Ologo julo,
Alagbara, 0lusegun, ‘WO la yin.

2 Laisimi, laiduro, ni idakeje,


O njoba LO, O ko si se alaini;
Giga ni idajo Re bi oke nla,
Ikuku Re b‘isun ire at‘ife.

3 f O nte gbogbo eda alaye lori


Nipa imisi Re won ngbe igbe won
A ndagba, a ngbile bi ewe igi
Asi nro; sugbon bakanna l‘Olorun

4 f Baba nla Ologo Imole pipe


AWON angeli Re wole l‘ese Re
Iyin wa la mu wa, JO ran wa l‘owo
K‘a ler‘ogo imole to yi O ka
Amin

100
7.4.7.4.5.7.4.
Ki iru awon ti of fe igbala re ki o ma wi nigbagbogbo pe:
"Ki a gbe Olorun ga. ‖ OD. 70:4.

1 f O ba ogo, alafia,
U no feran Re;
Ife na ki y‘o dekun,
Un o sunmo 0;
N‘tori O ti gbebe mi,
O ti gb‘ohun mi;
O ka iwe aya mi,
O da mi n'de.

2 Fun idasile yi ni
Un o korin Re;
Gbogb‘ay o okan mi ni
Un o mu fun O;
mp ‘Gbat‘ese min ke kikan,
O da mi lare:
mf ‘Gba mo pe O nikoko,
O gbebe mi.

3 f Gbgogb‘ojo aye mi ni
Un o fi yin O;
Mo le gbe O ga ninu
Okan mi yi:
Aye wa n‘nu okan mi
T'IWO y‘o ma gbe!
Ayeraye kuru ju
Lati yin Q.
Amin.

101 8.8.6.6.6.6.8.
E yin Olu wa. OD. 11.1:1.

1 f E yo loni pel‘ohun kan,


E korin igbega soke
Eyo, e yin Oluwa wa,
T‘ apa Re mu igbala wa,
Ise ife npokiki
Titobi oruko Re.
Olorun kan laelae
To ti fanu Re han:
K‘eniyan mimo Re juba Re,

2 mp ‘Gba ‘banuje de, a kepe


O si gbo gbogb‘ aroye wa
Gbekele boti wu kori,
Agbeniro ni ife Re;
mf Orin iyin ‘segun
Lokan wa y‘o ko si;
Gbogb‘ ohun y‘o ko pe;
―E yin Olorun wa‖;
K‘eniyan mimo Re juba Re.

3 f E yo, loni pel‘ohun kan,


E korin igbega soke;
E yo, e yin Oluwa wa;
T‘apa Re mu igbala wa;
Ise ife npokiki
Titobi oruko Re;
Olorun kan laelae
To ti fanu Re han;
K‘eniyan mimo Re juba Re.
Amin.
102 7.9.7.9. & Ref.
Emi o ma yin oruko Re nitori iseun - ife
Re ati otito Re OD. 138:2.

1 f Y in Olurapada re
F‘ogo Poruko Re titi lae!
Oloto li on sa je,
ff F‘ogo Poruko Re titi lae!
Gb‘oruko Re ga! F‘ogo
F‘oko Re;
Korin Aleluya titi lae!
Gb‘oruko Re ga!
F‘ogo f‘oko Re!
Korin ‘yin s‘Oluwa titi lae!

2 mf Fun ‘bukun to nfi fun wa!


F‘ogo f‘oruko Re titi lae!
B‘ or‘-ofe Re ti po to,
F‘ ogo f‘oruko Re titi lae!

3 cr Ko ha se o l‘ore bi?
mf F‘ogo Poruko Re titi lae!
Kil‘o ku k‘O se fun o?
F‘ogo Poruko Re titi lae!
4 cr Ife wo lo po bayi?
mf F‘ogo f‘oruko Re titi lae!
cr Alafia bayi wa bi?
mf F‘ogo f‘oruko Re titi lae.

5 ff Ki ahon mi tu lati
F‘ogo f‘oruko Re titi lae!
K‘emi lat‘ ayeraye
F‘ogo f‘oruko Re titi lae!
Amin.

103 8.8.8.5.
Gbe Oluwa ga pelu mi,
ki a si jumo gbe oruko Re leke. OD. 34:3.

1 f Y in Oluwa, eyin mimo


Awa ti je ni ‘gbese to?
Je k‘a mu gbogbo ini wa
Wa pelu ayo.

2 mf Jesu l‘Oko t‘o daraju


O nfun wa l‘okun l‘oju ‘ja
Ibi kan ko le de ba wa
‘Gbat‘ a gbekele.

3 Gbeke yin le, eyin mimo


Olododo l‘Olorun wa,
Ko s‘ohun to le, ya awon
T‘ O fe l‘odo Re.

4 mf F‘ore ofe Re pa wa mo
K‘a le tubo faramo O
Titi ao fi de ‘nu ogo
At‘ ayo l‘orun.
5 ‘Gbana l‘ao de ibi mimo
‘Gbana l‘a o si di mimo
Ayo nla ti a ko so
Niy‘ojetiwa.
Amin.

104 C.M. & Ref.


Eni ti o fe wa, ti o si we wa ninu eje
Re A uro ninu ese wa:
Tire li ogo ati ijoba lae ati lae:
Amin. Ifi.1:5-6.

1 mf Gbo orin awon ayanfe


Orin iyin titun;
T ‘od‘agutan t‘a se logo
Eyi ni orin won:
F ―Ogo f‘Eni to fe wa,
To f‘eje Re we wa,
To w‘ese at‘ebi wa nu
Nibi ‘san iye ni.‖

2 mf A fo aso wa n‘n‘eje Re
O si funfun laulau;
Imole t‘O tan s‘okan wa
F‘ipa oto Re han.

3 f A segun nipa eje Re


‘Gbat‘ esu gbogun de,
Agbara otito Kristi
Lo f‘okun s‘apa wa.

4 Ka juba Od‘agutan na
Baba ‘ye on mole
Tire l‘ogo, ola, ipa,
‘Joba at‘agbara.
Amin.

105 8.7.8.7.D.
Ohun opolopo eniyan nwipe, Alleluya. Ifi. 19:6.

1 mf Gbo orin ‗yin dida aye,


T‘egberun orile nko,
Orin didun bi t‘angeli,
O ndun bi omi pupo,
―Bukun, ogo, ipa, ‗gbala
Fun Olorun lor‘ite,
Baba, Omo, Emi mimo
Olola ‗lainipekun
2 mf Lati ebute otutu
Lor‘ olubuluku ‗le
Lat‘ opolopo eniyan
Ilu alawo pupa,
‗Lawo dudu t‘a da n‘ide,
Funfun ti o po niye,
Ominira alarinkiri
De ‗le awon Arabu

3 mf Lati ebute otutu


De ile ti o mooru,
Awon olokan gbogbona
Awon olokan gbigbona
Leba okun Pasifik;
Lati ‗opo aimoye okan
Onigbagbo alayo,
Awon to nsona bibo Re,
Won fere de sion‘ na

4 cr Akojo orile-ede,
Lat‘inu eya ahon,
Gbo, won nkorin iyin titi,
Gbo orin ologo ni,
O b‘afonifoji mole,
O si ndun lori loke,
F 0 ndun siwaju tit‘o fi
Kun ibugbe Olorun.

5 p Gbo, didun orin na dapo


Mo orin awon t‘orun,
Awon t‘o koja n‘nu ‘danwo
Sinu isimi loke,
cr Won wo aso ailabawon,
mf Imo ‘segun lowo won,
Won nfi duru ko Hosana,
Ni ‘waju Olorun won.

6 f ―Ogo fun Eni t‘o fe wa,


T‘O we wa n‘nu eje Re.
K‘oba, alufa, ma korin
Si Baba, Olorun wa.
K‘eeyan mimo on Angeli,
Ko Aleluya titi:
Asegun orun apadi:
Olodumare joba.‖
Amin.

106 P.M.
Ewe ati agba, nwon duro niwaju ite .
Ifi. 20:12.
1 mf A wa fori bale fun / O Jesu,
‘Wo ti s‘Olori Ijo awon / eniyan Re,
Ijo ti mbe laye yi ati lo / run pelu;
Ale/luya.

2 p ' Wo t‘oku, t‘o si jin/de fun wa,


T‘o mbe lodo Baba bi Ala/gbawi wa
K'OGO at‘olanla/je Tire
Ale/luya.

3 Mf Ati li ojo nla Pen/tikosti


Ti o ran Parakliti / si aye
Olutunu nla Re ti/ mba wa gbe;
Ale/luya

4 F Lat‘ ori ite Re l‘o/ke orun


L‘o si nwo gbogbo awon o/jise Re
T‘o si nsike gbogbo awon Aje/riku Re
Ale/luya

5 f A fi iyin at‘ olanla f‘o/ruko Re,


P N‘tori iku gbogbo awon o/jise Re,
Nigbogbo ile Yo/rubi yi:
Ale/luya
Amin

107 8.7.8.7.4.7.
Nje fun Oba ayeraye, aidibaje, airi,
Olprun kansoso, ni ola ati ogo
Wa fun lae ati laelae. A min
I Tim. 1:17.

1 f O go fun Olorun Baba,


Ogo f‘Olorun Qmo,
Ogo fun Olorun Emi,
Jehofa, Metalokan;
f Ogo, Ogo.
B‘ayeraye ti nkoja.

2 f Ogo fun Eni t‘o fe wa,


T‘o we abawon wa nu;
Ogo fun Eni t‘o ra wa,
T‘o mu wa ba On j‘Oba;
ff Ogo, Ogo,
Fun Od‘agutan t‘a pa.

3 f ―Ogo,‘bukun, iyin laelae!


L‘awon ogun orun nko;
―Qla, oro, ipa, ‘joba!‖
L‘awon eda fi nyin I,
ff Ogo, ogo,
Fun Oba awon oba.
Amin.

108 7.7.7.7.
A wa si nyin oruke re laelae.
OD. 44:8.

1 mf F ‘oruk‘ Olorun loke,


T‘O lagbara at‘ola,
Olorun ibigbogbo,
N‘iyin ati ogo wa.

2 F‘oruko Krist‘ Oluwa,


Om‘Olorun ti a bi,
Krist‘ t‘O da ohun gbogbo,
Ni k‘a san ‘yin ailopin.

3 F‘Olorun Emi Mimo,


Ni k‘iyin pipe wa lae,
Pelu Baba at‘Omo.
Okan l‘oruko, Togo.

4 Orin t‘a ti ko koja,


T‘ao si ma ko lae leyi;
Ki awon iran ti mbo
Dapo korin didun na.
Amin.

109 7.7.7.7.
Ogo ni fun Olorun loke orun.
Lk. 2:14.

1 f E fi ogo fun Baba,


Nipa Eni ti a wa;
O ngbo adura ewe,
O nf‘eti si orin won.

2 f E fi ogo fun Omo,


Kristi, ‘Wo ni Oba wa;
ff E wa, e korin s‘oke,
S‘Od‘agutan elese

3 f Ogo fun Emi Mimo,


Bi ojo Pentikosti;
Ru aya awon ewe,
F‘orin mimo s‘ete won.
4 ff Ogo ni l‘oke orun,
Fun Eni Metalokan;
Nitori ihin rere,
Ati ife, Olorun.
Amin.

110 7.7.7.5.
Awon eni irapada Oluwa yio pada,
won a si wa si Sioni ti awon ti orin.
Ikanu ati ofo yio si fo lo. Isa. 51:11

1 f Olorun Metalokan.
Oba ile at‘okun
Gbo ti wa bi a nko
Orin iyin Re

2 f ‘Wo imole l‘owuro,


Tan ‘mole Re yi wa ka
Jeki ebun rere Re,
M‘aya wa bale.

3 f ‘Wo‘ mole nigb‘orun WO


K‘a ri idariji gba Ki alafia
Orun F‘itura fun wa.

4 f Olorun Metalokan!
Isin wa l ‘aye ko to!
A nreti lati dapo
MO awon t‘orun.
Amin.

111 L.M.
Nibe ni Oluwa gbe pase ibukun,
ani iye lailai. OD. 133:3.

1 f Baba orun ‘jinle ‗fe Re,


L‘o wa Oludande fun wa;
p A wole niwaju ‘te Re,
mf Na ‘WO ‘dariji Re si wa.

2 f ‘Omo Baba t‘O d‘eniyan


Woli, Alufa, Oluwa,
p A wole niwaju ‘te Re,
mf Na ‘wo igbala Re si wa.

3 f Emi at‘ayeraye lae,


Emi ti nji oku dide,
P A wole niwaju‘te Re,
Mf Na ‘wo isoji Re si wa.
4 f Jehofa, Baba, Omo, Emi,
‘ Yanu, 'jinle, Metalokan;
p A wole niwaju‘te Re,
mf Na 'wo Emi ‘ye Re si wa.
Amin.

112 . 6.6.6.8.8.
Oluwa, iwo li o ye lati gba ogo, Ola
ati agbara. ifi.4 :11

1 mf Baba Eleda Wa,


Af‘ife gbadura;
Eni t‘O fun wa ni
Ona, oto, iye;
Cr Fi anu ro ‗jo ‗bukun Re
S‘ori awa ti njosin yi.

2 mf Baba Eleda wa,


A s‘okan wa paya;
Okan ominira wa,
F Nyin O lopolopo;
Mi imisi Re s‘okan wa,
K‘ orin ‗yin wa le bu jade

3 mf Baba Eleda wa,


Cr ‗Wo ri iberu wa
T‘o pamo l‘okan wa,
P T‘o nf‘omije soro;
Cr Ko wa lati gbekele O
Si mu wa la ewu yi ja

4 mf Baba Elede wa,


Je k‘a f‘ahon wa yin,
‗Gba t‘ayo t‘o jinle
Kun gbogbo okan wa;
N‘nu gbogbo ayida aye,
Je k‘a r‘ona alafia
AMIN

113 CM.
A o si ma pe orukO RE ni Iyanu. Isa. 9:6

1 f Olorun Olodumare,
Baba, Omo, Emi,
Riri Eni t‘a ko le mo,
Eni t‘a ko le ri.

2 f Ye! Baba Olodumare,


K‘a wariri fun O,
Ni gbogbo orile-ede,
Li a o ma sin O.

3 f Olorun Omo, Qre wa,


p ‘WO t‘o ra wa pada
Ma JOWO wa, Olugbala!
Gba wa patapata.

4 A! Olorun Emi Mimo,


‘WO olore-ofe;
A be O, fun wa ni imo,
K‘a m‘Olorun n‘ife.

5 f Okansoso sugbon meta,


Eni Metalokan,
Olorun awamaridi,
Eni Metalokan!
Amin.

114 C.M
Ibukun, ati Ola, ati Ogo, ati agbara,
fun eniti ojoko lori ite ati fun
Odo-Agutan na lae ati laelae.
Ifi. 5:13.

1 mf A ko ‘rin s‘Omo Olorun,


p Odagutan t‘a pa;
Ti orun ati aye mbo,
T‘O ye lati joba.

2 Si O l‘awon Angeli nke,


L‘ekun gbogbo orun:
p ―Mimo, mimo, mim‘Olorun,
T‘ogo, at‘om‘ogun.

3 f Ijo Re li aye dapo,


di Lati ma kepe O;
Didan Olanla Olorun,
T‘O l‘agbara gbogbo.

4 Larin won ni gbogbo wa nfe


Lati yin eje Re;
Joba l‘aye ati l‘orun,
‘Wo Omo Olorun.
Amin.

115 6.6.6.6.8.8.
Oluwa, IWO li o ye loti gba ogo,
ati Ola, ati agbara. Ifi. 4:11.
1 f Baba, Eleda wa,
Gbo orin iyin wa
L‘aye ati lorun,
Baba Olubukun:
cr IWO L‘ogo ati iyin,
Ope, ati ola ye fun.

2 f ‘WO Olorun Omo,


T‘O ku lati gba wa;
Eni t‘O ji dide,
Ti O si goke lo:
cr Iwo l‘ogo, ati iyin,
Ope, ati Ola ye fun.

3 f Si O Emi Mimo,
Ni a korin iyin:
IWO t‘o f‘imole
Iye si okan wa;
cr IWO L‘ogo, ati iyin,
Ope ati ola ye fun.

4 p Mimo, mimo, mimo,


N‘iyin Metalokan:
L‘aye ati l‘orun,
f L‘a o ma korin pe,
cr IWO L‘ogo, ati iyin,
Ope ati ola ye fun.
Amin.

116 9.10.10.7. & Ref.


Emi o tun pada wa, Emi o si mu yin
LO S‘odo emi tikarami. Jn. 14:3.

1 mf Jesu mbo! ko oro ayo na,


Mbo f‘awon t‘O Feje Re rapada,
Mbo lati joba b‘Oluwa ogo.
Jesu y‘o tun pada wa.
F Jesu y‘o tun wa, y‘o tun pada wa,
Jesu y‘o tun pada wa,
Ho iho ayo na ka ‘bi gbogbo,
Jesu y‘o tun pada wa.

2 mf Jesu mbo; Oku yio jinde,


Awon ore y‘o pade pel‘ayo,
Won o goke s‘odo Re ni sanma,
Jesu y‘o tun pada wa.

3 Jesu mbo lati da‘yanfe nde,


Lati f‘ alafia f aye ija,
Ese aro, ‘banuje y‘o d‘opin,
Jesu y‘o tun pada wa.

4 Jesu mbo, ileri na j‘oto,


Tal‘awon die t‘a yan ti nsoto,
Ti nduro, ti nsona fun ibewo,
Jesu y‘o tun pada wa.
AMIN

117 10.8.10.7.10.11.10.7.
Kiyesi i, O mbo ninu awosanma. Ifi. 1:7.

1 ff Jesu mbo l‘ofurufu pel‘ayo,


F Ojo ayo! ojo ayo!
mf Awon t‘o fe yo fo lo pade Re,
f Ojo ayo! ayo nla.
Won yo pade Oluwa ni sanma,
Gbogbo wa pelu Jesu yo wa nibe,
Ao bo lowo aniyan at‘aro;
Ojo ayo! ayo nla!

2 mf Awon obi, omo yo tun pade;


F Ojo ayo! ojo ayo!
Arakunrin pelu arabirin,
Ojo ayo! Ojo nla
Won mbe l‘odo Krist‘ a ko ri won mo,
cr Ibanuje ni lilo won je fun wa;
Sugbon ao pade laipe pel‘ayo,
mf Ojo ayo! ayo nla!

3 Gbogbo wa ha setan fun bibo Re?


Ojo ayo! ojo ayo!
Qmode ati agba ha se tan!
Fojo nla! Ojp ayo!
A nfe lati wa l‘odo Re laelae
K‘a le ma wo oju ati ewa Re,
Eyin ara, e korin nitori
Qjo nla na t‘ao pade.

4 f Awon miran ko ni le ba wa ko
Orin ayo ti ojo na!
Sugbon gbogbo wa ni ayo mbe fun
Ff Ojo ayo! ojo nla;
Mf ‘Tori Jesu nduro sibesibe,
K‘a le mura tan nipa agbara Re,
Ninu ogo didan Re k‘a le ni
Ibugbel‘oke orun.
Amin.

118 15.15.15.15. & Ref.


Nitorina e ma sona;
nitori eyin ko mo wakati ti Oluwa nyin
yio de. Mat. 24:42.

1 mf Awa nsona, awa nduro titi ‘boji y‘o fi ya,


T‘Oluwa pelu awon ayanfe y‘o de n‘nu ogo,
Nigbati a o gbo ipe Olorun jakejado,
Oku n‘nu Kristi y‘o si ji lati wa l‘odo Re lae.
cr Awa nsona, awa nduro,
Fun imole ti ojo nla na,
Fun bibo Olugbala wa
Pelu awon ayanfe

2 mf Awa nwo ona fun bibo Oba wa nla Ologo,


Eni ti yo le ibi ati okunkun lo jina,
‘Gbat‘ ododo ati anu Re yio bori l‘aye
Ti asia Re yo si ma fe lori gbogbo aye.

3 Awa nfi ‘gbagbo wo ‘joba Re ti egberun odun,


Ati opo awn emewa Re ti a ra pada,
Okan wa si nkepe. ―Ma bo k‘a ba le ri ogo Re'
Ki a le ma ba gbe ninu ogo ti ayeraye.
Amin
119 C.M
Nitori ti o ti be awOn eniyan Rewo;
0 si da won ni ide Lk. 1:68.

1 f Gbo ‘gbe ayo! Oluwa de,


Jesu t‘a se ‘leri;
Ki gbogbo okan mura de,
K‘ohun mura korin.

2 O de lati t‘onde sile


L‘oko eru esu,
ff ‘Lekun ide fo n‘waju Re
Sekeseke ‘rin da.

3 mf O de larin ‘baje aye


Lati tan ‘mole Re.
Lati mu k‘awon afoju
Le foju won riran.

4 p Ode,‘Tunu fokan‘rora,
Iwosan f‘agbogbe!
cr Pelu ‘sura or‘ofe Re
Fun awon talaka.

5 f Hosana, Oba alafia,


Ao kede bibo Re;
Gbogbo orun y‘o ma korin
Oruko t‘a feran.
Amin.

120 8.7.8.8.7.7.7.7.7.
Ati emi, ati iyawo wipe, Ma bo Ifi. 22:17.

1 ff Iwo mbo wa, Oluwa mi,


IWO mbo wa, Qba mi,
Ninu itansan ewa Re,
Ninu titayo ogo Re,
O ye k‘a yo, k‘a korin;
per O mbo ni ila orun
Awon akede npo si,
per O mbo: Alufa ogo;
A ko ha ngbo ago Re ?.

2 p IWO mbo wa, IWO mbo wa


A o pade Re l‘ona
cr A o ri O, a o mo O,
A o yin O: gbogbo okan
L‘a o sipaya fun O;
f Orin ki leyi o je
Orin t‘o dun rekoja;
A o tu ‘fe wa jade
Si ese Re. Ologo.

3 mf IWO mbo wa, ni tabil‘ Re,


L‘awa njeri si eyi;
p T‘a mo p‘O npade okan wa
Ni idapo mimo julo
Eri ibukun ti mbo
cr Ko f‘iku Re nikan han,
At‘ife titobi Re;
Sugbon bibo Re pelu
T‘a nfe, t‘a si nduro de.

4 f Y‘o dun lati ri O njoba,


Oluwa mi, Olufe;
cr Ki gbogbo ahon jewo Re,
Iyin, Ola, ati ogo,
Ki won jumo fi fun O;
ff ‘WO Oga mi, Ore mi,
K‘o segun k‘o si gunwa
Titi de opin aye
Ninu ogo at‘ola.
Amin.

121 D.S.M. & Ref


Nitoto Emi mbo kankan. Amin Ifi. 22:20.

1 mp Ijo ti nduro pe
Lati ri Oluwa,
O si wa bakan na sibe,
Ko s‘alabaro fun!
Odun nyi lu Odun,
Ojo ngori ojo,
Sibe lairi Oluwa re,
O wa ninu ofo.
Ma bo, Jesu, ma bo.

2 mp Awon mimo l‘aye,


Opo won l‘oti ku;
p Bi won si ti nlo l‘okankan
L‘a te won gbe ‘ra won;
pp A te won lati sun,
Ki se l‘ainireti;
cr A te won lati r‘eju ni,
K‘ile ogo to mo,
Ma bo, Jesu ma bo!

3 Awon ota npo si,


Agbara esu nga;
Ogun ngbona, igbagbo nku,
Ife si di tutu
cr Y‘o ti pe to! Baba,
Oloto, Olore!
‘Wo ki y‘okoya omije
At‘ eje Ijo Re,
Ma bo, Jesu ma bo!

4 mf A nfe gbo ohun Re,


A nfe foju kan 0.
K‘a le gba ade at‘ogo
B‘ati ngba ore Re;
F Jo, wa m‘ese kuro,!
At‘egun at‘eri,
K‘o si so aye osi yi
D‘aye rere Tire
cr Ma bo, Jesu ma bo.
Amin.

122 8.7.8.7.8.8.7,
Ohun eniti o mi aye nigbana.
Heb. 12:26.

1 ff O luwa, agbara fo ‘hun


Bi ara l‘oke Sinai,
Awon Israeli gb‘ohun Re,
Won si gbon fun iberu;
Okunkun su biribiri,
Ati l‘otun atil‘osi
Ff Awon apata n faya

2 p Oluwa ife je irora


Lori oke Kalfari,
O gbe oju soke orun,
L‘akoko wahala Re;
Fun wa lo ru eru egbe
Fun wa l‘o teje Re sile,
T‘o si tu Baba l‘oju.

3 mf Oba ife at‘agbara


Oluwa eda gbogbo
Cr O npada bo ninu ogo
Lati wa gba ijoba;
Ff Ipe y‘odun, angel‘ y‘o ho,
Aleluya y‘o j‘orin won,
L‘ori esu at‘iku.
Amin.

123 6,4.6.4.6.7.6.4.
O ti to wakati nisisiyi fun yin
lati ji l‘oju orun. Rom. 13:11.

1 f Gbo ohun alore,


Ji araji
Jesu ma fere de,
Ji, ara, ji,
mf. Omo oru ni ‘sun,
Omp imole l‘eyin,
Ti yin l‘ogo didan,
Ji, ara, ji.

2 mf So f‘egbe t‘o ti ji,


Ara sora,
Ase Jesu daju,
Ara, sora.
p E se b‘Olusona
Ni ‘lekun Oluwa yin,
Bi O tile pe de,
Ara, sora.

3 mf Gbo ohun iriju,


Ara sise:
Ise na kari wa,
Ara, sise;
Ogba Oluwa wa,
Kun fun ‘se nigbagbogbo
Y‘o si fun wal‘ere,
Ara, sise
4 mp Gb‘ohun Oluwa wa,
E gbadura,
B‘efe k‘inu Re dun,
E gbadura,
p Ese mu ‘beru wa,
Alailera si ni wa,
Ni ijakadi yin,
E gbadura.

5 f Ko orin ikeyin
Yin ara yin,
cr Mimo ni Oluwa,
Yin, ara, yin
Ff Ki l'o tun ye ahpn
T‘o fere b‘Agenl‘ Korin
T‘ y‘o ro lorun titi
Yin, ara, yin.
Amin.

124 7.6.7.6.D.
Wo! Oko Iyawo n mbo, ejade LO
PADE RE. Mat. 25:6.

1 f Yo eyin onigbagbo,
Je k‘imole yin tan;
Igba ale mbo tete,
Oru si fere de,
Qko iyawo dide
_ O fere sun mo le,
Dide, gbadura; Sora
L‘oru n‘igbe y‘ota.

2 mp E be fitila yin wo,


F‘ororo sinu Won;
E duro de ‘gbala yin
Ipari ‘se aye:
mf Awon oluso nwipe,
"Qko ‘yawo detan
E pade Re, b‘O ti mbo
Pelu orin iyin.‖

3 cr Eyin wundia mimo,


Gbe ohun yin s‘oke
F Titi n‘nu orin ayo
Pelu awon Angel‘
Onje iyawo setan,
Lekun na yi sile,
ff Dide, arole ogo,
Oko iyawo mbo.
4 mf Jesu, ‘Wo ireti wa;
F‘ara Re han fun wa;
‘Wo orun t‘a ti nreti,
Ran s‘ori ile wa,
A gbe oWO wa s‘oke
Oluwa je k‘a ri
Ojo ‘rapada aye
T‘o mu wa d‘odo Re
Amin.

125 8.7.8.7.
Ife gbogbo orile-ede yio si de.
Hag. 2:7.

1 f W a, IWO Jesu t‘a nreti,


T‘a bi lati da nin‘de,
Gba wa l‘owo ‘eru at‘ese,
Je k‘a ri isimi Re

2 IWO n‘itunu Israel‘,


Ireti onigbagbo,
Ife gbogb‘orile ede
Ayo okan ti nwona.

3 ‘Wo t‘a bi lati gba wa la.


Omo ti a bi l‘Oba,
Ti a bi lati joba lae,
Jeki ijoba Re de.

4 Fi Emi Mimo Re nikan


Se akoso aya wa;
Nipa ekun itoye Re,
Gbe wa sori ite Re
Amin.

126 7.7.8.4.
Eniti o ba to mi lehin kiyo
rin ninu okunkun. Jn. 8:12.

1 mf Mole t‘o da gbogbo nkan,


Ni pipe, lati n‘okun,
cr K‘a pin, n‘n‘ ewa on ‘bukun Re,
Wa s‘odo wa.

2 f ‘Mole t‘o joba aye,


‘Mole t‘o fun wa n‘iye,
A! Imole t‘o n s‘atunda,
Wa s‘odo wa.
3 p Imole t‘O wa s‘aye
‘Mole t‘o nw‘oju eda
pp T‘o ku l‘okunkun b‘eniyan;
Wa s‘odo wa.

4 mf ‘Mole t‘o de ‘pa ‘rele


T‘o tun lo s‘oke giga,
T‘o si wa pelu wa sibe
Wa s‘odo wa.

5 mf ‘Mole t‘o n fun wa l‘oye


‘Mole t‘onse wa l‘ewa,
Imole tin fayo simi,
Wa s‘odo wa.

6 mp Mase je k‘ape, ari,


‘Gbat‘ a diju wa si O,
pp Eni ti O nfi suru kan ‘kun
Wole, ma bo

7 mf Tire ni gbogbo ‘re wa


Tiwa ni gbogbo ibi;
Jo, le won kuro lodo Re
Wa s‘odo wa.

8 Mu ‘se okunkun kuro;


Di wa ni ‘hamora Re,
cr K‘arin n‘nu‘mole k‘a ma so
Atunwa Re.

9 p Awa se O pupo ju,


cr Sibe, Tire l‘awa se,
Je k‘aye wa j‘orin si O,
Wa s‘odo wa.

10 Wa ninu ola-nla Re
di Ni titobi ‘rele Re,
ff Wa, gbogbo aye nke pe O,
Wa s‘odo wa.
Amin.

127 8.8.8.8.8.8.
Olurapada yio si wa si Sioni.
Isa. 59-20.

1 mf Sum‘odo wa Imanuel‘,
Wa ra Israeli pada,
p T‘o nsofo li oko eru,
Titi Jesu y‘o tun pada.
ff Eyo, e yo! Imanuel‘,
Y‘o wa s‘odo wa, Israel

2 mf Wa, opa Alade Jese,


K‘o gba wa l‘owo ota wa,
Gba wa l‘ow‘ orun apadi.
Fun wa ni ‘segun l‘ori ‘ku.

3 Sunmo wa,‘WO ila orun,


Ki bibo Re se ‘tunu wa,
Tu gbogbo isudede ka
M‘ese ati egbe kuro.

4 mf Wa, Omo, ‘lekun Dafidi,


‘Lekun orun y‘o si fun O
Tun ona orun se fun wa;
JO se ona osi fun wa.

5 Wa Oluwa alagbara,
T‘o f‘ofin fun eniyan Re,
Nigbani, l‘or‘ oke Sinai,
Ninu olanla pel‘ eru.
Amin.

128 L.M.
Emi o si tun pada wa. Jn. 14:3.

1 mf L ‘eba odo Jordani ni


Oni ‘ribomi nke wipe
F Oluwa mbo! Oluwa mbo,
E gbo ‘hin ayo! Qba mbo!

2 K‘ese tan ni gbogbo okan,


K‘Olorun ba le ba wa gbe;
K‘a pa ile okan wa mo
Ki alejo nla yi to de.

3 Jesu, IWO n‘igbala wa,


Esan, ati alabo wa,
B‘itanna l‘awa ba segbe
Bikose t‘ore-ofe Re.

4 S‘awotan awon aisan,


Gb‘elese to subu dide,
Tan ‘mole Re ka bi gbogbo,
Mu ewa aye bo s‘ipo.

5 K‘a fiyin f‘omo Olorun;


Bibo eni mu dande wa
Eni t‘a nsin pelu Baba
At‘Olorun Emi Mimo.
Amin.

129
E ma Sora, ki e si ma gbadura.
Mk. 13:33.

1 mf I wo Onidajo,
A fere duro na
Pelu ayo tabi eru
Ni ‘waju ite Re;
JO, pese okan wa
Fun ojo nlanla ni,
p Fi emi isora kun wa
At‘emi adura.

2 f K‘a ma wo ona Re
L‘akoko aimo ni;
Ni gbat‘ Iwq sokale
Ninu olanla Re
IWO Emi aiku,
Lati da wa l‘ejo
T‘IWO ti ogun Baba Re
At‘ ore-ofe Re

3 mf K‘a le ba wa bayi,
Ni gboran soro Re
K‘a ma te ‘ti s‘ohun ipe,
K‘a ma wo ona Re,
K‘a wa ipo ayo
T‘awon olubukun,
K‘a si sora nigba die,
Fun simi ailopin.
Amin.

130 6.6.6.6.8.8.
E ma wa ninu Oluwa nigbagbogbo.
Fili 4:4.

1 f O luwa ni Oba,
E, bo Oluwa yin,
Eni kiku, sope,
Y'ayo ‘segun titi,
Ff Gb‘ok an at‘ohun yin soke
"E yo‖ mo si tun wi, ―E yo‘

2 Olugbala joba,
Olorun otito,
‗Gbat‘ O we ‗se wa nu
O g‘oke lo joko
3 O mbe l‘odo Baba
Titi gbogbo ota
Yio teri won ba
Nipa ase Tire

4 Yo n‘ireti ogo
p Onidajo mbo wa,
Lati mu ‘ranse Re
Lo ‘le ayeraye.
A fegbo ‘hun angel nla naa
ff Ipe y‘odun wipe, ―E yo ‖
Amin.

131 8.7.8.7.4.7.
Kiyesi i, O mbo li awosama. Ifi. 1:7.

1 mf Oluwa l‘awosanma,
O mbo l‘ogo l‘ola Re,
Enit‘a pa fun elese.
Mbo pelu Angeli Re;
ff Aleluya!
O was‘aye wajoba.

2 Gbogbo eda, wa wo Jesu,


Aso ogo l‘a WO fun;
P Awon t‘o gan, awon t‘o pa
T‘o kan mo agbelebu.
Pp Won o sokun,
Bi won ba ri Messiah.

3 Awon apa iya t‘O je


Han li ara didan Re,
Awon eni irapada,
Wole, fun t‘ayo t‘ayo;
Pel‘ ayo nla
L‘a nwo awon apa na.

4 Irapada t‘a ti nreti,


O de pelu ogo nla;
Awon ti a gan pelu Re
Y‘o pade Re loj‘ orun!
ff Aleluya,
Ojo Olugbala de.

5 Beni, Amin! k‘a juba Re,


Lor‘ ite Re ailopin,
Olugbala gba agbara;
Ogo at‘ ijoba Re,
Jah, Jehofa,
Olorun aiku, ma bo!
Amin.

132 8.7.8.7.8.8.7.
A o si ji awon oku dide li aidibaje
I Kor. 15:52.

1 f O lorun! kini mo ri yi!


Opin de f‘ohun gbogbo!
Onidajo araye yo,
O gunwa n‘ite ‘dajo,
ff Ipe dun, iboji si tu,
Gbogbo awon oku sile,
p Mura lo ko emi mi.

2 mf Oku‘nu Krist‘ y‘o ko jinde


Nigba ‘pe ‘keyin ba dun,
Won o lo ko l‘awosanma,
Won o fi ayo yi ka;
Ko s‘eru ti y‘o b‘okan won;
Oju Re da impoe bo
Awon ti o mura de.

3 p Sugbpn elese t‘on t‘eru!


Ni gbigbona ‘binu Re,
Won o dide, won o si ri
Pe, o se, won ko ba mo;
pp Ojo ore ofe koja;
Won ngbon niwaju ‘te ‘dajo,
Awon ti ko mura de.

4 cr Olorun, kini mo ri yi!


Opin de f ohun gbogbo,
Onidajo araye yo,
O gunwa n‘ite ‘dajo,
p L‘ese agbelebu mo nwo,
‘Gbat‘ ohun gbogbo y‘o koja,
cr Bayi ni mo nmura de.
Amin.

133 8.8.8.8.7.7.6.6.8.
Oluwa awon omo ogun.
On na li Oba Ogo. OD. 24:10.

1 f E gbe ori yin si oke,


Eyin ‘lekun ayeraye,
Wo! Oba nla, Ologo mbo,
Lati gunwa lori ‘te Re
Tani Qba ogo yi?
mp Tani Qba ogo yi?
cr Oluwa t‘O ni‘pa,
Asegun l‘oju ‘ja,
Asegun ‘joba okunkun.

2 mf E gbe ori yin si oke,


‘Lekun Pearl at‘ita wura,
Wo! Qba nla, Ologo mbo,
Ki keke ogun Re to de:
Tani Oba ogo na?
Tani Oba ogo na?
Oluwa ‘won‘m ogun
Olorun Ologo,
On li Oba ayeraye.

3 On pelu Baba at‘ Emi,


Won je okan na titi lae,
Awon angeli se l‘Oba,
Won nte riba n‘waju‘te Re
On ni Oba ogo na,
On ni Oba ogo na,
Je k‘aye juba Re,
K‘a si fiyin wa fun
Titi aye ainipekun.
Amin.

134 5.7.6.4. Ref.


Wo o, oko iyawo mbo. Mat 25:6.

1 Oko‘yawode!
‘Yawo Od‘agutan dide!
A gbo igbe l‘oru,
Dide, ye sun!
F Wo! oko iyawo de,
Wo! oko iyawo de,
Wo! oko iyawo de,
Jade lo pade Re!

2 mf Ase ‘yawo
Se tan, mura sile;
Ki o ba le wonu
Paradise.

3 cr D‘iju s‘aye
Ati ona re gbogbo,
Dide yara jade
LO pade Re

4 Dide korin,
Isegun re bere.
A n‘omije re mi,
‘Banuje tan.
Amin.

135 8.7.8.7.
Kiyesi i, Emi mbo kankan, ere mi si mbe pelu mi.
Ifi. 22:12.

1. J esu ti Baba ti gbega


Lat‘ ipilese aye,
On kanna yio pada wa
Lati se ‘dajo aye.

2 Wo! pipada bo Re daju,


A ki y‘o ha mura de E?
K‘a ba le ni ‘gbala kikun
L‘ojo ologo nla ni.

3 Y‘O f‘ara han l‘awosanma,


Gbogbo oju ni y‘o ri,
Ati awon t‘o kan mo ‘gi
Gbogb‘ aye ni y‘o jiyin.

4 Mo ‘le fi ‘gbagbo SQ wipe


Un o ba Jesu goke lo,
Si ‘joba egberun odun,
Ati ti ayeraye.

5 Sugbpn awon miran ki y‘o


Ba Oluwa wa goke,
Nitor‘ ise won ko lere,
Ti won se l‘oj‘aye won.

6 A nreti dide Re sibe,


‘WO ni ‘reti gbogb‘aye,
Ma bo, ‘WO Olugbala wa,
Mu wahala wa d‘opin.
Amin

136 8.7.8.7.
Ki enyin ki o mura sile;
nitori ni wakati ti enyin ko ro tele
li Omo-eniyan yio de. Mat. 24:44.

1 mf Aye ha nsaferi nipa


Bibo Krist‘ nigba keji?
F Bi orun on aye koja,
Oro na ki y‘o ye lae.

2 f Gege bi ojo Noa ti ri,


Beni wiwa Omo Eniyan;
‘Torina e je ka mura,
Ki oko ‘yawo to de.

3 Alabukun ni fun eni


Ti Kristi ba ti n sna;
On y‘o si fi se olori,
N‘nu ‘joba ayeraye.

4 ff A! ayo ojo ajinde!


Ayo na y‘o ti po to!
T‘oko, aya, omo, ara,
Yoo maa korin ‘rapada.

5 cr Jesu Oluwa ka wa ye
Si ‘joba ologo yi;
Ka le dapo m‘awon t‘orun;
Lati ma yin O laelae.
Amin.

137 8.7.8.7.D.
Ife gbogbo orile ede yio si de.
Hag. 2:7.

1 mf Imole awon t‘o joko


Leti ibebe iku,
Wa, jek‘ itan san ife Re
Tu okunkun aye ka;
Eleda orun on aye,
La si okunkun eda,
Ki aimoye wa le kuro,'
Ki oju wa le riran.

2 mf A nreti dide Re sibe,


‘Mole Re fun wa l‘ayo
O le gbogbo eru wa lo,
O fi ‘tunu f‘okan wa;
Wa, f oju-‘re Olorun han
Ti O fi ra wa pada;
Wa, Iwo Olugbala wa,
Mu ‘hin-rere wa fun wa.

3 cr Fi iyonu nla Re gba wa,


Olprun alafia;
Jek‘a mo adun igbala,
Dari ese wa ji wa,
Fi itoye irapada
Da okan ebi sile;

Mf To gbogbo okan ti nsako


Si ona alafia.
Amin.

138 7.7.7.7.
Olorun nikan li okan mi duro
je de; lati odo Re wa ni igbala mi.
OD. 62:1.

1 f W 0 Jesu t‘a ti nreti


Lati gba wa low‘ese.
‘Gbawo ni ‘gbala yo de,
Ti ao da ide ese?

2 mf ‘Wo Olugbala aye,


Wo ‘banuje okan san,
cr Gbe eru wuwo kuro,
M‘okan wa yo ninu ‘se Re.

3 mf Awon woli eke po,


Won si nfi ‘se ‘yanu han,
Lati tan ayanfe je;
cr Oluwa da won lekun.

4 Oluwa awa mbe O,


Fun wa l‘emi ‘farada,
Lati le sin O d‘opin,
Ka ma fara fun ‘danwo.

5 mf Mu okan t‘o sun soji,


Le ailera wa jinna,
K‘ale wa ni isokan
Titi ao fi ri O.

6 f Oluwa Olubukun,
Lodo Re ni ayo wa,
Fun wa l‘ore-ofe Re
K‘oma ba wa gbe titi.
Amin.

139 7.7.7.7.D.
Emi o si tun pada. Jn. 14:3.

1 f Iwo mbo wa, Oluwa;


Iwo mbo wa, Oba mi;
cr Ninu ‘tansan ewa Re,
Ni titayo ogo Re
Mura dee, e mura dee,
Oko ‘yawo fere de,
L‘oru ni igbey‘o ta,
Mura lo ko O, okan mi.
2 mf Wundia t‘o s‘oloto
Ti mura nigba gbogbo
Igba ayo sun mole,
Igba awe y‘odopin.

3 mf Iwo mbo wa nitoto,


A o pade Re lona
A o ri O, a o mo O
N‘idapo mimo julo.

4 mf Wundia mewa l‘ayan,


Marun pere l‘o yege,
mp Marun ko ni ororo,
p Ina emi n won ti ku.

5 mp ‘Binu Re tobi pupo


Si awon t‘o gbagbe Re;
Ewure apa osi
L‘a o se won nikeyin.

6 mf Jowo se wa l‘ayanfe,
Ki ale baO joba;
Angeli l‘ao ba k‘egbe
N‘gba t‘a ba gbe aiku wo.
Amin.

140 L.M.
O mbo, lati se idajo aye.
OD. 96:13.

1 f Oluwa mbo; aye yo mi,


Oke y‘o sidi n‘ipo won;
At‘ irawo oju orun,
Y‘o mu imole won kuro.

2 f Oluwa mbo; bakanna ko


p Bi o ti wa n‘irele ri;
Odo-agutan ti a pa,
pp Eni-iya ti o si ku.

3 f Oluwa mbo; li eru nla,


L‘owo ina pelu ija
L‘or‘ iye apa Kerubu,
Mbo, Onidajo araye

4 mf Eyi ha li eniti nrin,


Bi ero l‘opopo ayo?
Ti a se ‘nunibini si?
pp A! Eni ti a pa l‘eyi?
5 mf Ika; b‘e wo ‘nu apata,
B‘e wo ‘nu iho, lasan ni;
F Sugbpn igbagbo t‘o segun,
ff Y‘o korin pe, Oluwa de.
Amin

141 8.7.8.7.8.7.
Ji iwo Eniti o sun. Efe. 5:14.

1 mf W o oju sanma ohun ni,


Wo lila orun oro,
F Ji l‘oju orun, okan mi
Dide k‘o si ma sora!
Olugbala, Olugbala,
Tun npada bo wa s‘aye

2 O pe ti mo ti nreti Re
L‘are l‘okan mi nduro
Aye ko ni ayo fun mi
Nibiti ko tan ‘mole
Olugbala, Olugbala,
‘Gbawo ni ‘Wo o pada?

3 mf Igbala mi sun m‘etile


Oru fere koja na
p Je ki nwa nipo irele
Ki ns‘afoju sona Re
Olugbala, Olugbala,
Titi un o fi r‘oju Re.

4 mf Jeki fitila mi ma jo,


p Ki nma sako kiri mo,
Ki nsa ma reti abo Re
Lati mu mi lo s‘ile;
Olugbala, Olugbala,
ff Yara k‘o ma bo kankan
Amin.

142 6.6.6.6.8.8.
Oru bukoja tan, ile si fere mo. Rom. 13:12.

1 Oru bu koja tan


Qsan ku si dede;
Iboju fere ya
T‘o bo Olugbala;
Sanma ti o di wa loju
L‘a fere tu kakiri na.

2 f E gb‘ori yin soke,


Igbala sunmo ‘le,
Wo biorun ti ran,
Oju orun mole;
ff Eniyan mimo, e si ma so;
Oluwa fere fara han.

3 B‘eniyan nrerin yin,


Ti won ko fe gbagbo,
Eyin gb‘oro Re gbo,
On ko le tan yin je
Nigbati aye ba koja,
Eyin o ri ogo Re na.

4 Fun yin ni Oluwa,


Pese ile didan;
Ko si ‘kanu nibe
Kik‘ ayo l‘okun ‘be;
Mf Eyin mimo, bere si ‘yo,
E fere gbohun Angel‘ na.
Amin.

143 C.M.
Kiyesi i, emi mbo kankan Ifi. 22:7.
1 f J esu kigbe pe, ―Emi de,
T‘emi ti ife nla‖
Okan mi dahun pe, ―Ma‘bo‖,
K‘o mu igbala wa.

2 Wa, gba oran Baba Re ro;


Si mu ogo Re ran;
F Wa, ji oku iranse Re
K‘o si so won d‘otun.

3 Ma bo wa ‘larin ogun Re
Lati gb‘oruko won;
K‘o si m‘ajo kikun pada
Lati y‘ite Re ka.

4 Olurapada, wa kankan,
Mu ojo nla ni wa.
mf Wa, k‘okan wa ma ba daku,
Nitori pipe Re.
Amin

144 8.7.8.7.4.7.
Wakati mbo, ninu eyiti gbogbo
awon ti o wa ni isa oku
yio gbo ohun Re,
Won si jade wa. Jn. 5:28-29.
1 f Ojo ‘dajo, ojo eru!
Gbo bi ipe ti ndun to!
O ju egberun ara lo
O si nmi gbogbo aye.
p Bi esun na
Y‘o ti damu elese!

2 mf Wo Onidajo l‘awo wa,


T‘o wo ogo nla l‘aso.
Gbogbo won ti nwo ona Re.
‘Gbana ni won o ma yo
P Olugbala,
Jewo mi ni ijo na.

3 f Ni pipe Re o ku o ji
Lat‘ okun, ile, s‘iye:
Gbogbo ipa aye y‘o mi,
Won o salo loju Re.
p Alaironu,
Yoo ha ti ri fun o?

4 mf Esu ti ntan o nisiyi,


Iwo ma se gbo tire,
‘Gbati oro yi koja tan,
Y‘o ri o ninu ina;
p Iwo ronu
Ipo re ninu ina!
5 p Labe ippoju, at‘egan,
K‘eyi gba o n‘iyanju;
Ojo Olorun mbo tete,
‘Gbana ekun y‘o d‘ayo,
F A o segun
Gbati aye ba gbina.
Amin.

145 S.M.
Gbogbo oju ni yio ri i. Ifi. 1:7.

1 O nidajo mbo wa,


Awon oku jinde,
Enikan ko le yo kuro
‘Nu mole oju Re.

2 Enu ododo Re
Yio da ebi fun
Awon t‘o so anu Re nu;
Ti won se buburu.

3 ―Lo kuro l‘odo mi


S‘ina ‘ti ko l‘opin
Ti a ti pese fun
T‘o ti n sote simi

4 Iwo ti duro to!


Ojo na o mbo wa,
L'aye at‘orun o fo lo
Kuro ni wiwa Re.
Amin.

146 7.7.7.7.
Tani Oba ogo yi? OD. 24:8.

1 mf E yin t‘o gb‘ oke orun


E so ―T a l‘Oba ogo‖
Ta l‘oga julo nibe?
T‘o si l‘agbara gbogbo?

2 Od‘agutan nikan ni,


L‘o pe oye na ni t‘On;
On l‘o wa lori ite,
On si ni Oba ogo.

3 Ihin nla; Jesu l‘Oba,


On nikan l‘o si joba;
W‘odo Re t‘eyin t‘ore
E wole niwaju Re.

4 Je k‘aye k‘o r‘erin Re,


Je ki won ko lati sin;
Angel‘ nyo l‘oruko Re,
Gbogbo eda orun nsin.

5 A yin O, ‘Wo t‘Angel‘ n sin


Od‘Agutan Olorun,
Ma joba titi laelae,
Oba ye O, Oluwa.
Amin.

147 C.M.
E pese Okan nyin sile- I Sam. 7:3.

1 f J esu t‘o ga julo l‘orun,


Ipa Re l‘o d‘aye;
‘Wo f‘ogo nlanla Re sile,
Lati gba aye la.

2 O w‘aye ninu irele


mf Ni ara osi wa;
p Nitori k‘okan t‘o rele
Le t‘ipase Re la.
3 f Wiwa Re ya angel‘ l‘enu,
Ife t‘o tobi ni;
Eniyan Lanfani iye
Angeli se, ko ni.

4 f Nje araye yo; sa yin de,


ff E ho iho ayo:
Igbala mbo fun elese;
Jesu, Olorun ni.

5 Oluwa, je ki bibo Re,


Nigba erinkeji,
Je ohun ti nduro de,
K‘o le ba wa l‘ayo.
Amin.

148 8.8.8.6.8.8.8.8. & Ref.


Ogo ni fun Olorun loke orun.
Lk. 2:14.

1 f Ogo f‘Olorun lok‘orun,


Ogo; ogo ni fQlorun
Ogo f‘Olorun lok‘orun,
Li orin wa loni
Orin ti owuro ayo
Ti a bi Omo Dafidi
Ti ogun orun ko; awa.
Si fe dapo mo ogun na.
Ogo, fOlorun lok‘orun
Ogo, fOlorun lok‘orun
Ogo, ogo, ogo, ogo,
Ogo, fOlorun loke.

2 f Ogo f Olorun lok‘orun


Ogo, ogo ni f‘Olorun
Ogo f‘Olorun lok‘orun
Li orin wa loni.
Anu ti a nri gba fi han
Bi ife Re ti tobi to.
Je ki a gb‘ohun wa soke
Korin iyin Olugbala.

3 f Ogo f‘Olorun lok‘orun


Ogo, ogo ni f‘Olorun
Ogo f‘Olorun lok‘orun
Li orin wa loni.
p Je ki awa le duro pe
Niwaju ‘te Olugbala
K‘a korin pe l‘awon angel‘,
At‘awon eni ‘rapada.
Amin.

149 10.10.10.D.
Sa wo o, mo mu ihinrere ayo nla fun yin wa. Lk.2:10.

1 f Ji, ‘wo Kristian, k‘o ki oro ayo


Ti a bi Olugbala araye;
Dide, k‘o korin ife Qlorun
T‘awon Angeli nko n‘ijo kini;
Lat‘ odo won n‘ihin na ti bere;
Ihin Om‘Olorun t‘a bi s‘aye.

2 mf ‘Gba na l‘a ran akede angeli;


T‘a so f awon olus‘agutan pe,
―Mo mu ‘hinrere Olugbala wa
T‘a bi fun yin ati gbogbo aye,
Olorun mu l‘eri Re se loni
A bi Olugbala, Krist‘ Oluwa.

3 mf Bi akede angel‘ na ti so tan,


Opolopo ogun orun si de;
Won nkorin ayo t‘eti ko gbo ri,
Orin Aleluya gba orun kan,
Ogo ni f‘Olorun l‘oke orun,
Alafia at‘ife s‘eniyan.

4 A ba le ma ranti nigbagbogbo
Pe, ‘fe Olorun l‘o gba ‘raye la,
K‘a to ‘se Jesu t‘o ra wa pada,
Lat‘ ibuj‘ eran de or‘agbelebu;
K‘a toro or‘-ofe k‘a le te le,
Titi ao tun r‘oju Re Qlorun.

5 f Nigbana ‘gba ‘ba de orun lohun


A o korin ayo t‘irapada;
Ogo Eni t‘a bi fun wa loni,
Y‘o ma ran yi wa ka titi laelae;
A o ma korin ife Re titi,
Oba angeli, Oba eniyan.
Amin

150 8.7..8.7.4.7.
Awa si wa lati f‗ori bale fun.
Mat. 2:2.

1 f Eyin angel‘ l‘orun ogo,


To yi gbogbo aye ka;
E ti korin dida aye,
E so t‘ibi Mesaiah
F E wa josin
Fun Kristi Oba titun.

2 mf Eyin Oluso-agutan
Ti nso eran yin l‘oru,
Imanueli wa ti de,
Irawo Omo na ntan.

3 F Amoye, f ero yin sile,


Wo ‘ran didan lokere!
Wa ‘reti nla orile‘ de,
E ti ri irawo Re

4 mf Onigbagbo ti n teriba
Ni ‘beru, at‘ireti,
L‘ojiji l‘Oluwa o de
Ti yio mu yin re ‘le.

5 A nwo b‘om‘owo nisi‘yi,


Y‘o gba ite Baba Re,
Ao ko gbogb‘ aye s‘odo Re,
Gbogb‘ekun yo wole fun.
Amin.

151 7777.7777.77.
Nitori a bi Omo kan fun wa,
a fi Omo kunrin kan fun wa. Isa. 9:6.

1 Gbo eda orun nkorin:


―Ogo fun Oba t‘a bi‖ .
P ―Alafia l‘aye yi‖
Cr Olorun ba wa laja,
F Gbogbo eda nde l‘ayo,
E gberin, at‘oke wa,
Kede pel‘angeli pe
A bi Kristi ni Betlehem‘.
Gbo Eda orun nkorin
Ogo fun Oba t‘a bi.

2 Kristi t‘a nyin l‘ogo l‘orun,


Kristi Oluwa titi lae,
Ni igbeyin, wo, o de,
Omo inu wundia!
W‘Olorun di eniyan!
Olorun di eniyan
O dun mi k‘o b‘eeyan gbe
Jesu, Imanuel‘ wa.

3 Wo, Alade alafia!


Wo o, orun ododo!
Omu ‘mole iye wa,
‘Lera mbe li apa re,
O bo ‘go re s‘apakan,
A bi k‘eniyan ma ku;
A bi ko gb‘eniyan ro,
A bi k‘o le tun won bi.

4 Wa ‘reti oril‘ede,
F‘okan wa se ‘bugbe Re,
Nde, Iru Qmo ‘birin,
Segun esu ninu wa,
Pa aworan Adam re,
F‘aworan Re dipo re,
Adam‘ ‘keji lat‘oke,
Gba wa pada s‘ife re
Amin.

152 C.M.
Oluwa joba OD. 97:1.

1 f A yo b‘aye! Oluwa de,


K‘aye gba Oba re?
cr Ki gbogbo okan mura de,
K‘aye korin s‘oke.

2 Ayo b‘aye! Jesu joba,


cr E je k‘a ho fayo,
Gbogbo igbe, omi, oke,
Won ngberin ayo na.

3 mf K‘ese on ‘yonu pin l‘aye,


K‘egun ye hu n‘ile,
O de lati mu ‘bukun san,
De ‘bi t‘egun gbe wa.

4 O foto at‘ife joba,


O jek‘orile‘de
Mo, ododo ijoba Re,
At‘ife ‘yanu Re
Amin.

153 C.M. & Ref.


A oma pe Oruko Re ni Imanueli Mat. 1:23.

1 f Ayo kun okan wa l‘oni,


Abi omo Oba!
Opo awon ogun orun
Nso ibi re loni!
ff E yo, Olorun d‘eniyan!
O wa joko l‘aye!
Oruko wo l‘o dun to yi
Imanuel‘

2 mp A wole n‘ibuje eran,


N‘iyanul‘a josin,
cr Ibukun kan ko ta yi yo,
Ko s‘ayo bi eyi.

3 mf Aye ko n‘adun fun wa mo


‘Gbati a ba nwo O
L‘OWO wundia iya Re,
‘W o Omo iyanu.

4 f Imole lat‘inu ‘Mole,


Tan ‘mole s‘okun wa!
K‘a le ma fi isin mimo
se ‘ranti ojo Re.
Amin.

154 6.6.10.5.6. & Ref.


Eje ki a lo tara si Bethlehem.
Lk. 2:15.

1 f Wa eyin olooto!
L‘ayo at‘isegun,
Wa ka lo, wa ka lo si Betlehem
Wa kalo woo
Qba awon Angel‘
F E wa kalo juba Re
E wa kalo juba Re
E wa kalo juba Kristi Oluwa

2 Olodumare ni
Imole ododo,
P Ko si korira inu wundia
F Olorun papa
Ti a bi, t‘a ko da!

3 f Angeli, e korin
Korin itoye Re!
Ki gbogbo eda Orun si gberin,
Ogo fOlorun
L‘oke orun lohun!

4 f Nitoto a wole
F‘Oba t‘a bi loni,
Jesu IWO li awa nf ogo fun!
‘Wo Omo Baba,
T‘ogbearawa wo!
Amin.
155 8.7.8.7.
IWO Betlehemu, IWO ko kere
julo nin ‘awon Omo alade Juda. Mat. 2:6

1 f Ilu t‘o dara po l‘aye


Betlehem‘, ‘wo ta won yo,
Ninu re l‘Oluwa ti wa
Lati joba Israel‘.

2 Ogo ti irawo ni ju
Ti orun owuro lo,
Irawo t‘o kede Jesu
Ti a bi ninu ara,

3 Awon ‘logbon ila-orun


Mu ‘yebiye ore wa;
E wo bi won ti fi wura,
Turari, ojia fun.

4 Awon ebun iyebiye;


Turari, n f‘okan s‘oke,
Wura won nkede Oba won,
Ojia nfi ‘boji Re han.

5 Jesu, ‘Wo ti keferi nsin


Li ojo ifihan Re;
Fun O, Baba l‘a f ogo fun
Ati fun Emi Mimo.
Amin.

156 7.7.7.7.7.7.

Nigbati nwon si ri irawo na,


nwon yo ayo nlanla. Mat. 2:10

1 f B ‘awon ara igbani


Ti f ayo ri ‘rawo na,
Bi won ti f inu didun
Tele ‘mole didan re,
Be, Oluwa Olore
Ni k‘a mu wa d‘odo Re

2 mf Bi won ti fi ayo LO
Si ibuje eran na,
Ti won si wole nibe,
F‘Eni t‘orun t‘aye mbo,
Gege be ni k‘ama yo
Lati wa site anu.

3 Bi won ti mu ore wa
Si ibuje eran na,
Be ni k‘a f ayo mu wa
Ore t‘ese ko baje,
Mu isura gbogbo wa
Sodo Re, Jesu Oba.

4 p Jesu mimo, pa wa mo.


L‘ona toro l‘ojojo
Cr ‘Gbat‘ ohun aye ba pin
M‘okan wa de ilu, ti
‘Rawo ko nsamna mo,
‘Biti won nwo ogo Re.

5 ff Ni ‘lu orun mimo na,


Won ko wa imole mo,
‘Wo l‘orun re ti ki wo,
‘Wo l‘ayo at‘ade re,
Nibe titi l‘ao ma ko
Aleluya s‘Oba wa.
Amin.

157 C.M.
Nitori a bi Olugbala fun yin loni
ni ilu Dafidi, ti ise Kristi Oluwa. Lk. 2:11.

1 B i awon 0lus‘agutan
Ti ns‘agbo won l‘oru;
Angel‘ Oluwa sokale,
Ogo ran yin won ka.

2 Eru ba won pupo, sugbon


O ni - ―E ma beru,
Ihin ayo ni mo mu wa
Fun yin at‘araye,‖

3 Fun yin n‘iluDafid‘, loni,


N‘idile Dafidi,
A bi Olugbala ti se
Kristi, Oluwa wa;

4 Eyi ni y‘o j‘ami-Eyin


O ri om-Owo na,
A fi oja we, a si te
Si ibuje eran.

5 Bi angel‘ na ti soro tan


Opo awon angel‘
Fo de, won si nyin Olorun
Won nkorin ayo pe
6 Ogo ni f‘Olorun loke
Alafia l‘aye,
K‘ife ‘nurere s‘eniyan
Bere, laini opin.

Amin.

158 8.7.8.7.D.
A bi Olugbala fun yin loni
ti ise Kristi Oluwa. Lk. 2:11.

1 A f‘ope fun Olorun wa


To ran Omo Re w‘aye;
K‘ayo gba gbogbo aye kan
F‘omo nat‘abi loni.
E ho, eyo, gbogb‘eniyan,
E fiyin f Olorun wa,
E ho, eyo, onigbagbo;
K‘iyin gba okan wa kan.

2 A fope fun Olorun wa


Fun ‘fe nla to ni si wa;
O ran Olugbala w‘aye,
Lojo oni awa nyo.

3 Ki gbogb‘ eso inu igbo,


Koko, ope on roba,
Gbogbo isura ‘nu ile
Ba wa fiyin f‘Oba wa.

4 Je ki eja inu ibu


At‘eye oju orun,
Ki gbogbo eranko igbe,
Wa fiyin f Oluwa wa.

5 Bi a tin je ti odun yi,


A mbe O, Metalokan,
Jek‘a le wa fiyin fun O
Niwoyi odun to mbo.
Amin.
159 10.8.10.8.
Gbogbo ahon ni ki o ma jewo pe,
Jesu Kristi ni Oluwa. Fili. 2:11.

1 Omo n‘bujeranl‘omo Maria,


Alejo, Oluwa aye,
Omo to ru gbogbo asise wa
Ati awon abuku wa.

2 Nigbakan L‘OMO Mimo julo yi


F‘irele gbe‘nu ayeyi;
Nisiyi gege b‘Olurapada
O ni ‘segun lori Ota.

3 Awon woli so asotele re;


Awon angel ri lor‘ite Olugbala,
‘Wo ni iyin ye fun;
Layo l‘awon Tire y‘o wa.
Amin.

160 8.7.8.7.
A ti li aye alafia; ife inu
rere si eniyan. Lk. 2:14.

1 Alafia f‘aye at‘eeyan


L‘orin t'awon angel‘ ko;
Awon Olus‘agutan gbo
T‘ikede ibi Kristi.

2 Ni on oke Judea
N‘imole ‘rawo nla tan
Lati s‘amona fun awon
Ti nwa ebun ‘yanu yi.

3 Awon amoye meta ni


Ri imple nlanla na;
Won mu ebun wa f‘Omo na,
Wura, turari, ojia.

4 Leba ibuje eran na


Won juba fun Oba won,
N‘irele won f‘ebun lele
F‘eni to mu ‘gbala wa.

5 Bi odun ti nyi lu odun


L‘a tun nbi Krist‘ ni titun
N‘nu okan awon omo Re,
B‘angeli ti so tele

6 A nri ‘rawo na nisiyi


B‘akoko ta bi Kristi;
Ki ‘bukun Kristi je tire
B‘odun ti nyi lu odun.
Amin.

161 C.M.
Lati wasu ihinrere fun awon otosi,
lati ?s awotan awon onirobinuje Okan,
lati kede idasile fun awon igbekun. Isa. 61:1.

1 Gbo iro orin angeli


Ti ndun yi aye ka;
A bi Olugbala s‘aye
Om‘Olorun d‘eniyan.

2 A bi Olugbala loto
Fun gbogbo agbaye;
Lati da wa n‘de low‘esu
Kuro ninu egbe.

3 Opo ogun orun si yo


Fun ‘Mole to deyi,
Ogo f‘Olorun lok‘orun,
Alafia f‘eniyan.

4 A ha mo b‘o ti soro to
Lati f‘ite sile,
Lati mu ago kikoro
Fun ‘rapada en‘yan!

5 E fi ope fun Olorun


Fun ife nlanla yi
To ran Omo Re kansoso
Wa s‘aye osi yi.

6 ‘Wo Omo nat‘a bi loni


F‘alafia fun aye,
F‘ore-ofe Re ba wa gbe
At‘ayo ibi Re
Amin.

162 6.6.8.6.6.8.
Nwon si wa logan, nwon si ri
Omoo OWO na. O dubule ninu
ibuje eran. Lk. 2:16.

1 E yin onirele,
Ayaro, amukun,
E sare wa, mase beru;
Jesu isura wa,
T‘ife Re ko n‘iwon,
Ni ibuje‘ ran l‘ate si.

2 B‘awon amoye ni Tile


F‘ebun nla fun
Awon malu pelu si fun
Ni koko fun ‗busun‘
Jesu gba ore won
N‘itelorun n‘ibujeran.

3 E yara, je k‘ alo.
San gbese ‘yin wa! fun;
Isin wa ni On ki yo gan;
Eni ti ife Re
Si le s‘ampoa wa
S‘ibuje ‗ran ti a te si.
Amin.

163 11.10.11.10
Awa ti ri irawo Re ni ila orun,
Awa si wa lati f‘oribale fun u. Mat. 2:2

1 mf Irawo owuro Ologo julo,


Tan si okunkun wa, ran wa lowo;
Irawo ti ns‘amona ero l‘ona,
Sin wa de ibi t‘Olugbala wa.

2 mp O dubule jeje ni ibusun Re,


A te sile larin awpn eran;
Awon angeli njuba Re b‘O ti nsun,
Eleda, Oba, Olugbala wa.

3 mf Ko ha ye k‘a mu ore didun wa fun;


Orun didun t‘o nta sansan t‘Edomu‘,
Isura lat‘oke, pearli lat‘ okun,
Ojia lat‘igbo, wura inu ‘le

4 mp Lasan n‘isura je, lasan l‘ebun wa,


B‘a ko ba sin l‘emi at‘ otito.
mf ‘Yebiye loju Re b‘a f‘okan wa fun;
cr Owon julo l‘adura otosi.

5 mf irawo Owuro Ologo julo,


Tan si okunkun wa, ran wa L‘OWO;
Irawo ti nsamona ero l‘ona,
Sin wa de ibi t‘Olugbala wa.
Amin.

164 8.7.8.7.8.7.
Awao mayo, inu wayio si ma dun OD. 118:24.

1 f Onigbagbo, ebu s‘ayo,


Ojo nla l‘eyi fun wa;
E gbo bi awon Angeli
Ti nf‘ ogo fun Olorun:
Alafia, Alafia
Ni fun gbogbo eniyan.

2 ff Ki gbogbo aye ho fayo,


K‘a f‘ogo fun Olorun,
Omo bibi Re l‘o fun wa
mf T‘a bi ninu Wundia:
En‘ Iyanu, En‘ Iyanu
Ni Omo t‘a bi loni.

3 f Ninu gbogbo rudurudu,


On ibi t‘o kun aye,
Ninu idamu nla ese
L‘Om‘ Olorun wa gba wa:
Olugbimo, Olugbimo,
Alade Alafia.

4 f Olorun Olodumare
L‘abi, bi omo titun;
Baba! Eni ayeraye
L‘o di alakoso wa:
ff E bu s‘ayo, E bu s‘ayo,
Omo Dafidi joba.

5 p O wa gba wa L‘OWO ese,


O wa d‘onigbowo wa
Lati fo itegun Esu
A se ni Oba ogo:
F E ku ayo, E ku ayo,
A gba wa L‘OWO iku.
Amin.

165 8.7.8.7.8.7.
A wa si wa foribale fun Mat. 2:2.
1 ff O nigbagbo, e bu s‘ayo!
Ojo nla l‘eyi fun wa;
K‘orun fayo korin kikan,
K‘ igbo at‘odan gberin.
ff Eho! Eyo! Eho! eyo!
Okun at‘odo gbogbo!

2 f E jumo yo, gbogbo eda,


Laye ati lorun;
F Ki gbogbo ohun alaye
Nile loke yin Jesu.
E f‘ogo fun, E f‘ogo fun,
Oba nla t‘a bi loni!

3 ff Gb‘ohun yin ga, ―Omo Afrik‖


Eyin iran Yoruba;
Ke ‗Hosana!‖ l‘ohun goro
Jake-jado ile wa.
K‘oba gbogbo, K‘oba gbogbo
Juba Jesu Oba wa.

4 f E damuso! E damuso!
ff E ho ye! k‘e si ma yo.
Itegun esu fo wayi,
―Iru-omobirin‖ de!
Aleluya! Aleluya!
Olurapada, Oba.

5 E gb‘ohun yin ga,


Serafu, Kerubu, leba ite;
Angeli at‘ eyin mimo,
Pelu gbogbo ogun orun,
F Ebawayo! Ebawayo!
Odun idasile de.

6 Metalokan, Eni Mimo,


Baba, Olodumare,
Emi Mimo, Olutunu,
Jesu, Olurapada,
Gba iyin wa, Gba iyin wa,
‘Wo nikan l‘ogo ye fun.
Amin.

166 L.M.
Mo mu ihin ayo nla fun nyin wa.
Lk. 2:10.

1 f Ojo ayo nlanla na de,


Eyi t‘ araye ti nreti;
cr Nigbat‘ Olugbala w‘aye
Nigbat‘ a bi ninu ara.

2 f Olus‘agutan ni papa
Bi won ti nso agutan won,
Ni ihin ayo na ko ba.
Ihin bibi Olugbala.

3 Angel‘ iranse Oluwa


L‘a ran si Won, alabukun,
Pelu ogo t‘o tan julo,
Lati SO ihin ayo yi.

4 mp Gidigidi l‘eru ba won,


Fun ajeji iran nla yi;
F ―Ma beru‖ l‘oro iyanju
T‘o t‘enu Angeli na wa.

5 A bi Olugbala l‘oni,
Kristi Oluwa aye ni;
N‘ilu nla Dafidi l‘o wa,
p N‘ibuje eran l‘atesi.

6 f ―Ogo fun Olorun‖ l‘orin


Ti eniyan y‘o ko s‘orun:
Fun ife Re laini opin,
T‘o mu alafia w‘aye.
Amin.

167 7.6.7.6.D.
Olorun si li Oro na,
Oro na si di ara. Jn. 1:1,14.

1 mf E ji, eyin,eniyan
E ma se sun titi;
F A! Imole wa nlanla
On li o yo de yi.
Orun n‘imole ara,
Jesu ni ti Okan?
Ireti awon baba
Yio hade lasan?

2 p O de k‘ewon ese tu
O de k'okunkun lo;
F Eyo ijoba Jesu
O ni rorun pupo,
E je k‘a mu ore wa
K‘a juba Oba wa
Awon amoye mu wa
A ki o mu wa bi?

3 f Je k‘a fi Okan wa fun,


K‘o te ‘te Re sibe;
K‘a fi ohun gbogbo fun
K‘a si se ife Re.
ff Eyo! Eyo! E tunyo!
Jesu Oluwa de
F‘otosi at‘oloro,
Kristi Oluwa de.
Amin.
168 7.7.7.7.
Ogo ni fun Olorun loke Orun.
Lk. 2:14.

1 f ‘Gba Jehofa da aye,


cr ‘Gbat‘ o Soro t‘o.si se
Awon Angeli nkorin
ff Aleluya gb‘orun kan.

2 mf Orin ‘yin l‘a ko l‘oro


Gbat‘ a bi Olugbala;
cr Orin‘yin ni asi ko
Nigbat‘ o digbekun lo.

3 p ‘Gbat‘ aye y‘o koja lo,


Iyin o gb‘ojo na kan;
‘Gbat‘ a o d‘aye titun,
Orin iyin l‘a o ko.

4 Awa o ha dake bi
Titi joba na o de?
Beko! Ijo o ma ko
Orin mimo at‘iyin.

5 Eniyan mimo l‘aye,


Nf‘ ayo korin iyin na;
Nipa ‘gbagbo ni WON nko,
Bi won o ti ko l‘oke.

6 Nigba emi o ba pin


Orin ni o segun ‘ku;
Ninu ayo ailopin
Won o ma korin titi.
Amin.

169 8.7.8.7.
Angeli na sidahun o si wi fun u pe,
Emi Mimo yio to O wa, ati agbara
Oga-Ogo yio siji bo O:
nitorina ohun Mimo ti a o ti
inu re bi, Omo Olorun li a o ma pe e. Lk. 1:35.

1 f M awo ‗le, Jesu t‘a nreti,


T‘a bi lati gba ni la!
Gba wa l‘ow‘ese at‘eru;
K‘a r‘isimi ninu Re.

2 mp Ipa at‘itunu Israel‘;


Ireti awon mimo;
Olufe gbogbo orile,
Ayo okan ti nreti.

3 mf A bi 0 lati gb‘eda la,


Eniyan-sugbon Olorun
Lati joba lae ninu wa,
mp Mu ‘joba rere Re wa.

4 mp Nipa Emi Re t‘o wa lae,


Nikan joba ninu wa;
Nipa ‘toye Re t‘o po to,
Gbe wa s‘ite ogo Re
Amin.

7.7.7.7. Omo Alade Alafia.- Isa. 9:6.

1 O de, Kristi Oluwa,


Lat‘ ibugbe Re l‘orun,
Lat‘ ite alafia,
O wa si aginju wa.

2 Alade Alafia
De, lati ru ‘ponju wa,
O de, lati f‘imole
Le okun oru wa LO.
Amin.

171 7.5.7.5. D.
Ki a le ma yin Olorun l‘ogo
li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi
I Pet. 4:11.

1 mf Baba je nya Odun yi


Si mimo fun O,
N‘ipokipo t‘o wu O
Lati fi mi si,
Nko gbodo ko ‘banuje
Tabi irora,
Eyi sa l‘adura mi,
Ogo Toko Re

2 mf Om‘ owo ha le pase


Biti on y‘o gbe?
Ife Baba le du ni
L‘ebun rere bi?
‘Jojumo n‘lwo nfun wa
Ju b‘a ti bere,
Laidu wa l‘ohun t‘o le
Gbe oko Re ga.
3 cr Ninu anu, b‘Iwo ba
Fun mi, li ayo,
T‘o je k‘ewa aye mi
Tubo tan jade,
Je k‘okan mi ma f‘ayo
Korin iyin Re,
Ohun t‘ola ba mu wa,
―Ogo f oko Re.‖

4 p B‘O mu ‘ponju wa ba mi
T‘ona mi s‘okun
T‘ere mi di adanu,
Ti ilemi kan;
Je ki nranti bi Jesu
Se de ‘nu ogo,
Ki ngbadura n‘nu ‘ponju,
mf ―Ogo f‘oko Re.‖
Amin

172 D.S.M.
Nigba die ewe, e o si ri mi.
Jn. 16:16.

1 mp Leyin odun die,


Leyin lgba die,
di A o ko wa jo pel‘awon
p Ti o sun n‘iboji
cr Oluwa, mu mi ye
Fun ojo nlanla na;
Jo, we mi ninu eje Re
p Siko ese milo.

2 mp Leyin ojo die


L‘aye okunkun yi,
di A o de‘bi orun ko si mo,
Ile dara dara.

3 mp Leyin iji die,


L‘ebute giga yi,
di A o de b‘igbi ko si mo,
Ti irumi ko si

4 mp Leyin ‘yonu die,


Leyin ‘pinya die,
di Leyin ise on omije,
A ki o sokun mo.

5 mf Ojo ‘simi die,


L‘a ni tun ri l‘aye,
mp A o de ibi isimi
Ti ki o pin laelae.

6 f Ojo die l‘o ku,


On o tun pada wa,
mf Eniti O ku, k‘awa le pe
K‘a ba le ba joba.
Amin.

173 S.M
I gba mi mbe li OWO Re.
OD. 31:15.

1 mf Igba mi d‘owo Re,


Mo fe k‘O wa nibe;
Mo f‘ara, ore, emi mi
Si abe iso Re.

2 mp Igba mi d‘owo Re
Eyi t‘o wu k'o je,
Didun ni tabi kikoro.
B‘O ba ti ri p‘o to

3 Igbami d‘owo Re,


Emi y‘o se beru?
p Baba ki o jek'omo Re
Sokun li anidi

4 mf Igba mi d‘owo Re,


Jesu t‘a kan mo gi;
p Owo na t‘ese mi dalu
Wa di alabo mi.

5 f Igba mi d‘owo Re,


‘Wo ni ngo gbekele,
Leyin iku, low‘ otun Re
L‘em‘ o wa titi lae.
Amin.

74 7.6.7.6.D.
Bakanna ni IWO, odun Re ko lopin OD. 102:27.

1 Apata ayeraye,
Enit‘o mbe laelae
Nigbakugba t‘iji nja,
‘ Wo ‘bugbe alafia:
Saju did‘aye wayi Iwo, mbe;
bakanna Ti t‘aye ainipekun
Ayeraye ni ‘Wo.
2 Oj‘ odun wa ri b‘oji
T‘o han l‘ori oke;
Bi koriko ipa‘do,
T‘o ru ti o si ku:
Bi ala tabi b‘itan
T‘ enikan nyara pa:
Ogo ti ko ni si mo,
Ohun t‘o gbo tan ni.

3 'Wo eniti ki togbe,


'Mole enit‘itan
Ko wa bi a o ti ka
Ojo wa k‘o to tan;
Je k‘anu Re ba le wa
K‘ ore Re po fun wa;
Si je k‘Emi Mimo Re
Mole si okan wa.

4 Jesu, f‘ewa at'ore


De ‗gbagbo wa l‘ade
Tit‘ a o fi ri O gbangba
Ninu ‗mole laelae
Ayo t‘enu ko le so,
Orisun akunya;
Alafia ailopin,
Okun ailebute
Amin.

175 8.7.8.7.
Ko wa lati ma ka iye ojo wa,
ki a lefi okan wa sipa Ogbon. OD. 90:12.

1 mf Ojo ati akoko nlo;


Won nsun wa s‘eti ‘boji
p Awa fere dubule na,
Ninu iho ‘busun wa.

2 mf Jesu ‘Wo Olurapada


Ji okan t‘o ku s‘ese:
cr Ji gbogbo okan ti nto gbe
Lati yan ipo iye.

3 mp Bi akoko ti nsunmo ‘le,


Je k‘a ro ‘biti a nlo
Bi lati r‘ayo ailopin,
pp Tabi egbe ailopin.

4 mf Aye wa nlo, iku de tan


pp Jesu so wa di abo Re,
mf K‘a ba O gbe, K‘a ba O ku,
pp K‘a ba O joba titi.

5 mp Aye wan koja b‘ojiji


O si nfo lo bi ‘kuku,
cr Fun gbogbo odun t‘o koja
Dariji wa, mu wa gbon.

6 mf Ko wa lati ka ojo wa,


Lati ba ese wa ja,
K‘a ma s‘are k‘a ma togbe
Tit‘ao fi ri ‘simi.

7 f Gbogbo wa fere duro na


Niwaju ite ‘dajo
ff Jesu ‘w o t‘o segun iku
Fi wa s‘apa Otun Re.

8 mf Ay wa nlo, iku de tan


Pp Olugbala, pa wa mo,
K‘a ba O gbe, k‘a ba O ku
F K‘a ba O joba titi.
Amin

176 CM.
Oluwa, IWO li o ti nse
ibujoko wa lati irandiron. OD. 90:1.

1 f O lorun t‘odun t‘o koja


Iret‘ eyi ti mbo;
Ib‘isadi wa ni iji
A t‘ile wa laelae.

2 mp L‘abe ojiji ite Re


L‘awon eniyan Re ngbe,
F Tito l‘apa Re nikanso,
Abo wa si daju.

3 mf K‘awon oke k‘o to duro,


Tabi k‘a to d‘aye,
f Laelae IWO ni Olorun
Bakanna, l‘ailopin!

4 Egberun odun l‘oju Re


Bi ale kan l‘o ri;
B‘iso kan l‘afemojumo
Ki orun k‘o to la.

5 Ojo wa bi odo sisan,


Opo l‘o si ngbe lo;
Won nlo, won di eni ‘gbagbe
Bi ala ti a nro ‘

6 f Olorun t‘odun t‘o koja,


Iret‘ eyi ti mbo,
Ma s‘abo wa ‘gba ‘yonu de
At‘ ile wa laelae. Amin.

177 C.M.
Nje Oluwa niyio ma se Olorun mi. Gen. 28:21.

1 mf Ollorun Betel‘ eni ti


O mbo awon Tire,
Enit‘ o mu baba wa la
Ojo aye won ja

2 p A mu eje at‘ebe wa
Wa iwaju ‗te Re,
Olorun awon baba wa
F Ma je Olorun wa

3 Ninu idamu aye yi


Ma to isise wa,
Fun wa ni onje ojo wa
At‘aso t‘o ye wa.

4 Na ojiji‘ ye Re bo wa
Tit‘ajo wa opin
Ati ni ‘bugbe Baba wa,
Okan wa o simi.

5 Iru ibukun bi eyi


L‘a mbere L‘OWO Re,
Iwo o je Olorun wa.
At‘ipin wa laelae.
Amin.

178 11.11.11.11. & Ref.


IWO ma beru, nitori mo wa pelu re. Isa. 41:10.

1 mf N ‘ibere odun yi, odun titun yi


Oro itunu de, ti nle eru lo
p Ohun keje jeje ti Baba Orun
cr Ododo l‘oro na, ti nm‘okan wa yo
f E ma tesiwaju, Omo imole,
Oro Re ko le ye, O nduro titi.

2 f ―Ma beru‖ l‘oro na, ―Mo wa pelu yin‖


Emi n‘iranwo yin at‘agbara yin,
Emi y‘o di yin mu, li owo ‘tun mi,
Mo pe yin, mo yan yin, lati je temi.

3 f Fun opo odun ti mbe niwaju wa,


Opo ni ipese t‘o ti seleri:
Ipese f‘alaini, f‘awon elese.
F‘awon t‘a npon loju, fun alailera.

4 mf Ko je fi wa sile, ko si ni ko wa,
Majemu Re daju ti ko le ye lae
ff A ro mo ‘le riyi, eru ko bawa,
Olorun wa ti to, fun odun ti mbo.
Amin.

179 8.7.8.7.4.7.
Olorun si wipe,..... Ki nwon ma wafun ami,
akoko ojo ati fun Odun.
Gen. 1:14.

1 f Oluwa alafia wa
L‘O pase t‘odun yipo;
Awa omo Re wa dupe
F‘ odun tuntun t‘ a bere
Yin Oluwa!
Oba nla t‘O da wa si.

2 mf A dupe fun ipamo wa


Ni odun ti o koja;
A mbebe iranlowo Re
Fun gbogbo wa l‘odun yi.
Je k‘ Ijo wa
Ma dagba ninu Kristi.

3 f K‘agba k‘o mura lati sin


L‘okan kan ni odun yi;
K‘awon omode k‘o mura
Lati s‘aferi Jesu.
K‘alafia
K‘o se ade odun yi.

4 f K‘Emi Mimo lat‘oke wa


Be le wa ni odun yi;
Ki Alufa at‘Oluko,
Pelu gbogbo Ijo wa
Mura giri
Lati josin f‘Oluwa.
Amin.

180 7.7.7.7.D.
Kili emi nyin? Jak.4:15.
1 mf Odun miran ti koja
Wawa l‘akoko na lo
Ninu eyi t‘a wa yi
P Yio s‘arimo opo;
Anu l‘o fi da wa si,
A ha lo anu na bi?
K‘a bi ‘ra wa ba se tan?
B‘a o pe wa l‘odun-ni.

2 f Aye bi ibi ija,


Egbegberun l‘o n subu;
mp Ofa iku l‘o si nfo,
A le ran s‘emi b‘iwo;
Nigb'a nwasu t‘a si n gbo
Oluwa je k‘a saro
P‘ayeraye sunmole
A nduro l‘eti, bebe

3 f B‘a gba wa lowo ese


Nipa ore-ofe Re.
Nje ‗ma bo‘ n‘ipe o je,
K‘ale LO, k‘ ar‘oju Re:
F‘eniyan Re l‘aye yi
K‘anu wa l‘odun titun;
Odun t‘o l‘ayo ju yi,
L‘eyi t‘o mu won de ‘le.
Amin.

181 C.M.
Je ki ise Re ki o han si awon Omo-odo Re. OD. 90:16.

1 mf Olorun at‘ ireti mi,


Oro Re l‘onje mi,
Owo Re gbe mi ro l‘ewe
Ati l‘odomode.

2 Sibe mo nrohun iyanu


T‘O nseni ododun;
Mo fi ojo mi ti o ku
S‘iso Tire nikan.

3 Ma ko mi, nigba ‘gbara ye,


Ti ewu baba mi,
Ff Ki ogo Re ran yi mi ka
Nigbati mo ba ku.
Amin

182 7.7.7.7.
Alaye, alaye on ni yio yin O,
bi mo ti nse loniyi. Isa. 38:19.

1 mf B ‘orun l‘aiduro ti rin,


La odun tio lo ja,
Be l‘opo ti dopin won
A ki o si ri won mo.

2 A so won l‘ojo laelae


Tiwon pari li aye;
Awa duro die na,
Y‘o ti pe to, a ko mo

3 f Gb‘ope f‘anu t‘o koja,


p Tun dari ese ji wa;
Ko wa b‘a ti wa, k‘a maa
Se ‘ranti aye ti mbo.

4 f Bukun fewe at‘agba,


F‘ifo Oluwa kun wa;
‘Gba ojo aye wa pin
K‘a gbe odo Re l‘oke.
Amin.

183 D.L.M.
O si pe oruko re ni Ebeneseri wipe:
Titi de ihin li Oluwa ran wa L‘OWO. I Sam. 7:12.

1 mf Oluwa at‘ igbala wa,


Amona at‘ agbara wa,
L‘o ko wa jo l‘ale oni,
Je k‘a gbe Ebeneser ro;
Odun t‘a ti la koja yi,
Ni on f‘ore Re de l‘ade,
Otun l‘anu Re l‘owuro;
Nje ki ope wa ma po si!

2 mf Jesu t‘o joko lor‘ ite,


L‘a fi Aleluya wa fun;
Nitori Re nikansoso
L‘a da wa si lati korin;
Ran wa l‘owo lati kanu
Ese odun t‘o ti koja;
Fun ni k‘a lo eyi ti mbo,
S‘ iyin Re, ju Odun t‘o LO.
Amin.

184 CM
Mu mi mo ona ti emi iba ma to. OD. 143:8.

1 mf Oluwa fi apa Re han,


Si jek‘ ar‘ogo Re,
Ki gbogbo wa ri ami Re,
K‘o m‘ okan lile TO.

2 di K‘aanu yo wa ninu ebi,


Gbogb‘ ese t‘a ti da,
Ki odun ti a bere yi,
Le pari pelu Re.

3 p Ran Emi Re lat‘ oke wa,


K‘alefe O julo,
K‘elese ti o n‘ife ri,
Le ko lati feni.

4 mp Nigbat‘ a ba de ‘waju Re,


N‘ ile ayeraye,
F Ki opo d‘ipo wa nihin,
Lati f iyin fun O.
Amin.

185 L.M
E fi iyin fun Oluwa. OD. 106:1.

1 mf A yin O. Oluranwo wa,


T‘ife Re wa bakanna lae,
OWO ike en‘ t‘o bere,
Ti o si pari odun wa.

2 mf Larin egbegberun ‘danwo,


A duro nipa ‘toju Re;
Nigbat‘ a si bojuw‘ eyin
A r OPO ohun fun iyin.

3 mf De‘hin li apa Re sin wa,


De ‘hin Fa rohin ahu Re;
di ‗Gbati a nrinl‘asale yi,
Anu bere orin titun.

4 mf Gb‘okan wagunle Jordani,


Won o tun gbe opo kan ro,
Gba won ba si d‘agbala Re,
Won o gb‘ am‘ ife ti ki ku.
Amin.

186 C.M.
Olorun si wipe, ki imole ki o wa
L‘ofurufu fun ami, fun akoko,
fun ojo, ati fun odun. Gen. 1:14.

1 mf Olorun wa, je k‘iyin Re


Gb‘ohun gbogbo wa kan;
Owo Re yi ojo wa po,
Odun miran si de.

2 Ebo wa ngoke sodo Re,


Baba, Olore wa:
Fun anu ododun ti nsan
Lati odo Re wa.

3 N‘nu gbogbo ayida aye,


K‘anu Re wa sibe:
B‘ore Re si wa si ti po,
Beni k‘iyin wa po.

4 N‘nu gbogbo ayida aye,


A nri aniyan Re;
JOWO, je k‘anu Re ‘kanna
Bukun odun titun.

5 B‘ayo ba si wa, k‘ayo na'


Fa wa si odo Re;
B‘iya ni, awa o korin
B‘ibukun Re pelu.
Amin.

187 7.7.7.7.
Igba mi mbe li OWOre. OD. 31:15.

1 mf Alakoso ti orun,
Alanu at‘Ologbon;
Igba mi mbe l‘ OWO Re,
Opin gbogbo l‘ase Re.

2 Ase Re l‘oda aye


Ati ibi mi pelu,
Obi, ile, on igba
Nipa Re ni gbogbo won.

3 p Igb‘ aisan on ilera,


Igba ise on oro,
Igba ‘danwo, ibinu,
Igba ‘segun, iranwo.

4 Igba iridi Esu,


Igba ‘to ‘fe Jesu wo,
Won o wa, won o si LO,
B‘ore wa orun ti fe.

5 ff Iwo Olore-ofe,
‘WO ni mo f‘emi mi fun,
Emi jewo ife Re,
Emi teriba fun O
Amin.

188 7.7.7.7.D.
Eyipada kuro ninu ona
buburu nyin; nitori kini eyin o seku.
Esek. 33:11.

1 mp Elese, e yipada,
Ese ti e o fi ku?
Eleda yin ni mbere
Tofeki e ba On gbe;
Oran nla ni O mbi yin,
Ise owo Re ni yin;
cr A! eyin alailope
Ese t‘ e o ko ‘fe Re?

2 p Elese e yi pada,
Ese ti o o fi ku?
Olugbala ni mbere;
Eni t‘O gb‘emi yin la;
Iku Re y‘o j‘asan bi?
E o tun kan mo ‘gi bi?
di Eni ‘rapada ese
Te o gan or‘ofe Re?

3 p Elese, e yi pada,
Ese ti e o fi ku?
Emi mimo ni mbere
Ti nfojo gbogbo ro yin;
E ki o ha gb‘ore Re?
E o ko iye sibe?
di Ati nwa yin pe, ese
T‘ e mbi Olorun ninu?

4 cr Iyemeji ha nse yin


Pe ife ni Olorun
E ki o ha gboro Re?
K‘e gba ileri Re gbo?
p W‘Oluwa lodo yin,
pp Jesu sun, w‘omije Re;
Eje Re pelu nke pe:
Ese ti e o fi ku?
Amin.

189 6.5.9.14.9.&Ref.
Nitori ti Oluwa mbo wa se idajo aye OD. 96:13.

1 mf Ojo nla kan mbo wa,


OJO nla kan mbQ;
Ojo nla kan mbo wa, nigbose,
T‘awon eniyan mimo at‘elese y‘o pinya,
Iwo ha setan fun ojo na?
cr O ha setan? O ha se tan?
O setan fun ojo idajo?
O ha setan? O ha setan?
Fun OJO ‘dajo.

2 f OJO didan kan mbo


Ojo na mbo wa,
ff Ojo didan ‘kan mbo, nigbose,
Sugbon didan re je ti awon t‘o fe Oluwa
IWO ha se tan fun ojo na?

3 p OJO ‘banuje mbo,


QJO na mbo wa,
OJO ‘banuje mbo nigbose
Ti elese y‘o gbo pe: LO, Emi ko mo yin ri‘
IWQ ha setan fun ojo na?
Amin.. .

190 8.8.8.
Nitoriti O mbo wa se idajo aye. I Kro. 16:33.

1 mf O jo ‘binu, ojo aro;


T asotele Woli ni se,
Ti orun at‘ aye njona.

2 f Iro iyanu, fere dun


Ja gbogbo iboji aye;
Gbogbo eda wa ‘waju Re.

3 cr Oro ti mbe ninu ‘wena,


p A ko Won sile lesese;
Lati fi ‘dajo f‘eniyan.

4 f Ikede, ‘rokeke b‘aye,


Won ji kuro n‘nu orun won
Lati je ‘pe Onidajo.

5 mf Onidajo ododo nla!


cr Fun mi l‘ebun ‘dariji Re,
p K‘ojo esan to de ba mi.
Amin.

191 L.M.
Nitorina awon eniyan buburu ki yio dide duro ni idajo. OD. 1:5
1 f Ojo ‗binu, ojo eru
T‘aye at‘orun y‗o fo lo,
di Kin‘ igbekele lelse?
p Y‘o se le y‘oju l‘ojo na?

2 f Nigbati orun y‘o kako


Bi awo tia f‘ina sun,
cr Ti ipe ajinde y‘o ma dun
ff Kikankikan, t‘eru t‘eru

3 A! l‘ojo na, ojo'binu.


T‘ eda yio ji S ‘dajo.
cr Kristi jo se‘gbekele wa.
di ‘Gbat‘aye, t‘orun ba fo lo
Amin.

192 11.11.11.9 & Ref


Nitori ailabawon li ebun ati ipe Olorun. Rom 11:29

1 f Ipe t‘o ni 'bukunl‘aoke orun


Ipe t‘o ni ‗bukun li emi npe wa,
O fi agbara fun eni ti n sare
Eni t‘o ba gbagbo, fun 0 ni.
ff Fun o ni ara fun O ni.
Gbekele 'leri Re to daju (ara mi)
FUN o ni, ma, fun o ni
Eni t‘o ba gbogbo, fun o ni.

2 mp O ti f‘eje Re ‗yebiye se ‗laja


Omo Olorun ti sise igbala
Gbogbo ise naa ti pari, o pari
Mf Lati gba 'bukun na, fun o ni.

3 Y‘o gba enl t‘o ba gbagbo la d‘opin,


Otito Olorun ti sise igbala
Gbogbo ise na ti pari, o pari
Mf Eni t‘o ba gbagbo, fun o ni

4 mp Ma siyemeji mo, wa‘ do Re loni,


Mf Kuro ninu ese re patapata
‗Tori anu Re nla, y‘o dariji o,
Y‘o si s‘amona re de orun

5 mp Lohun ni ‗le ogo ao korin ‗yin Re,


Mf Li ohun isegun; lae ati lae,
B‘ipe na tile pe, sibe titun ni,
Ff Ogo, Aleluya, fun o ni
Amin

193
7.6.8.6.7.6.11. & Ref.
Pe Kristi Jesu wa si aye lati gba eleese la.
I Tim. 1:15.

1 mf Mo ni Olugbala kan,
Owa lati orun,
P O ku fun mi ni Kalfari
Lati fi ‘fe Re han,
Cr Iru‘fe t‘On isimi
O nna ‘wo Re si o,
Wo ko ha ni gba Jesu ni nitire
Mf Wo ko ha ni je ki O gba o,
Oun y‘O je ore toto fun o,
Yio we okan re mo, yio si so di
pipe
Wo ko ha ni gba Jesu mi ni tire?

2 f Mo l‘Olugbala rere,
O ngb‘ ohun ipe mi,
cr O nru gbogbo wahala mi, '
Om‘ese mi duro,
mf O s‘oninure to be,
Ol‘anu at‘oto,
‘Wo ko ha ni gba Jesu mi nitire?

3 f Mo l‘Olugbala toto,
On y‘o ma ba mi gbe,
mf Yio si di owo mi mu
Titi uno fi gunle,
mp L‘ojo kan n‘nu ogo Re
f Uno r‘Olugbala mi,
Ara, ‘wo ko ha ni gba A l‘Oluwa.
Amin

194 8.7.8.7. & Ref.


Ma LO, ma si tun d'ese mo Jn. 8:11.

1 mf O gbo ohun Jesu t‘O nwi


cr Pe k‘o fi ese sile,
O ti mu ‘gbala ofe wa
Bi iwo ba je tele,
F Wa, tele Oolugbala re,
Fi ayo gba Olutunu;
Ohun Re npe o, asako,
Sa bere. ki o si gbagbo.

2 cr Ese t‘o ko f okan re fun


p Jesu t‘O ku l‘ori ‘gi?
cr O wipe, mo dariji
p, Gb‘agbelebu, tele mi.

3 mp Uno was‘odo Re, Jesu mi,


Uno fi aye mi fun 0.
mf Uno feran Re, Uno sin O,
cr Gba mi loni, Oluwa.

4 mf Jesu gba mi la, O gba mi.


mp B‘O ti leri lati se,
Gbogb‘ eni ese li o ru,
F Wa, y‘O si gba o pelu.
Amin.

195 6.6.6.5.& Ref


E wa s‘odo mi gbogbo Enyin ti n sise,
Emi o si fi isimi fun yin. Mat. 11:28.

1 mf Wa gba isimi re,


Mase je ‘rora mo,
di Wa s‘odo Jesu re,
Ma se jafara,
mp Adura, ng‘oke lo,
Angel‘ nteri won ba,
mf Aye dapo mo won,
Mase jafara.

2 p Okunkun l‘aye yi
Lala inu re po,
F Wa s‘agb‘ Olugbala
mf Mase jafara.

3 mf Gb‘eru ese re wa,


Jesu ti ku fun o,
F On y‘o t‘ewo gba o,
Mase jafara.

4 cr Igba ko duro pe,


Wawa l‘akoko nlo,
mf Idajo si mbo wa,
cr Mase jafara.

5 mf Wa, awa mbe o, wa;


F Wa, ye gb‘oke gb‘odo;
Wa mura fun ile,
Mase jafara.
Amin.

196 7.8.7. & Ref


Loni, bi enyin ba gbo ohun Re
e mase se aya yin le. Heb. 4:7.

1 mf Wa, nigbati Kristi npe o


Wa, ma rin ‘na ese mo,
Wa, tu gbogb‘ ohun t‘o de O
Wa, bere ‘re ‘je t‘orun.
F O npe o nisiyi,
Gbo b‘Olugbala ti npe,
O npe o nisiyi,
Gbo b‘Olugbala ti npe.

2 cr Wa, nigbati Kristi mbebe,


Wa, gbo ohun ife Re,
‘WO o ko ohun ife Re,
Wo o si ma sako ese

3 mf Wa, mase f‘akoko d‘ola,


Wa, ojo ‘gbala ni ‘yi,
Wa fi ara re fun Kristi,
Wa wo ‘le niwaju Re.
Amin.

197 10.10.10.
A se bi O ti wi tan, aye si mbe sibe.
Lk. 14:22.

1 f ―A ye si mbe!‖ ile Od‘agutan,


Ewa ogo re npe o pe ―Ma bo‖
p Wole, wole, wole nisisiyi.

2 Ojo lo tan, orun si fere wo,


Okunkun de tan, ‘mole nkoja lo,
P Wole, wole, wole nisisiyi.

3 Ile iyawo na kun fun ase;


F Wole, wole to oko ‘yawo lo;
cr Wole, wole, wole nisisiyi.

4 f O nkun! o nkun! ile ayo na nkun


Yara! mase pe ko kun ju fun O!
p Wole, wole, wole nisisiyi.

5 f ― Aye si mbe‖ ilekun si sile,


llekun ife, iwo ko pe ju,
p Wole, wole, wole nisisiyi.

6 f Wole, wole! tire ni Ase na.


Wa gb‘ebun ‘fe ayeraye lofe!
p Wole, Wole, wole nisisiyi.

7 f Kiki ayo lo wa nibe, wole!


Awon angeli npe o fun ade,
p Wole, wole, wole nisisiyi.
8 ff L‘ohun rara n‘ipe ife na ndun!
cr Wa ma jafara, Wole, ase na!
p Wole, wole, wole nisisiyi.

9 p K‘ile to su, ilekun na le ti


p ‘Gbanao k‘abamo! ―o se! o se!‖
cr O se, o se, ko s‘aye mo; o se!
Amin.

198 8.8.8.8.8.9.8.9.
Jesu ti Nasareti li o nkoja Lk. 18:37.

1 f E redi irokeke yi
Ti eniyan ti nwo koja?
‘ Jojumo n‘iwojopo na,
Eredi re, ti won nse be?
F Won dahun Fohun jeje Pe (2ce)
Di ―Jesu ti Nasareti l‘O nkoja. (2ce)

2 mf Tani Jesu? Ese ti On


Fi nmi gbogbo ilu bayi?
Ajeji Ologbon ni bi?
Ti gbogb‘ eniyan nto leyin?
p Won dahun l‘ohun jeje pe (2ce)
cr ―Jesu ti Nasaret‘ l‘O nkoja‖. (2ce)

3 Jesu On na l‘O ti koja


p Ona irora wa l‘aye
‘Bikibi t‘On ba de, won nko
Orisi arun wa ‘do Re
F Afoju yo, b‘o ti gbo pe; (2ce)
cr ―Jesu ti Nasaret‘ l‘O nkoja.‖ (2ce)

4 On si tun de! n‘ibikibi


Ni awa si nri ‘pase Re,
On nrekoja l‘ojude wa
O wole lati ba wa gbe,
F Ko ha ye k‘a fayo ke pe (2ce)
di ―Jesu ti Nasaret‘ l‘O nkoja.)2ce

5 Ha! e wa, eyin t‘orun wo!


f Gba ‘dariji at‘ itunu,
p Eyin ti e ti sako lo
cr Pada gba or‘ofe Baba,
Eyin t‘a-danwo abo mbe (2ce)
F ―Jesu ti Nasaret‘ l‘O nkoja‖ (2ce)

6 p Sugbon b‘iwo ko ipe yi,


cr Ti o si gan ife nla Re;
On yio peyinda si o,
Yio si ko adura re;
p ―Opeju‖ n‘igbenay‘o je (2ce)
pp ―Jesu ti Nasaret‘ ti koja‖ (2ce)
Amin.

199 6.4.64.
Loni bi enyin ba gbo ohun Re,
e mape se aya nyin le. OD. 95:7-8.

1 f Lonini Jesupe!
Asako wa,
p A! okan okunkun
Ma kiri mo.

2 f Lonini Jesu pe!


Gbo ohun Re
Ki ‘gba Re to koja
Teriba fun.

3 f Loni ni Jesu pe!


Sa asala,
p Iji igbesan mbo,
cr Iparun mbo.

4 f Loni ni Jesu pe!


JOWO ‘ra re;
Ni ‘gba anu ma je
K‘O binu lo.
Amin.

200 7.6.7.6.
Eniti o ba si to Mi wa, Emi ki yio taa
nu, bi o ti wu ki o ri. Jn. 6:37.

1 mf ―W a sodo Mi, alaare,


Un o fun yin n‘isimi,‖
p A! ohun didun Jesu,
Ti o p‘elese wa
cr O nso, ti Ore-ofe
Ati t‘alafia,
Ti ayo ti ko l‘opin,
T‘ ife ti ko le tan.

2 mf ―E wa.eyin omo Mi‖


Un o fun yin n‘imole,
p A! ohun ife JESU,
cr Tinle okunkun lo.
p Awa kun fun ‘banuje,
Ati s‘ona wa nu;
F Imole y‘om‘ayo wa,
Oro y‘o m‘orin wa.

3 mf ―E wa, eyin ti ndaku


Un o fun yin ni iye
p Ohun alafia Jesu
T‘o f‘opin s‘ija wa,
mf Oju ota wa koro,
Ija si le pupo
cr Sugbpn ‘Wo fun wa n‘ipa
f A bori ota wa.

4 mf Enikeni t‘o ba wa,


Emi ki o ta nu
P A! ohun suru Jesu
cr T‘o le ‘yemeji lo,
mf Ninu ife iyanu,
T‘o pe awa elese,
B‘a ti le je alaye
S‘odo Re, Oluwa.
Amin.

201 7.7.7.7.
E teti lele, ki e wa S‘odo mi. Isa. 55:3.

1 Yara, elese, k‘o gbon!


Ma duro d‘ojo ola;
Ma kegan ogbon, n‘tori
p Atunri re y‘o soro.

2 Yara lati wa anu,


Ma reti ojo pla,
Akoko re lekoja
K‘ise ale yi to tan.

3 f Yara, elese pada,


Ma reti ojo ola;
mp Ki fitila re to ku,
K‘ise igbala to tan.

4 f Yara lati gba‘bukun!


Ma duro o d‘ojo ola;
Ki egbe ma ba ba o
K‘ile ola to mo.
Amin

202 8.7.8.7.11.
Enikeni ti o ba sife, ki o gba
omi iye na lo fe Ifi- 22:17.

1 mf O tosi elese, e wa,


Wa ni wakati anu,
Jesu setan lati gba yin,
O kun f anu at‘ife.
cr O si le, se O mura tan, ma foya.

2 mf Eyin alaini, e wa gba


Ogo Olorun l‘ofe
Gbagbo toto, ronu toto
Or‘ofe ti o nfa wa
cr Wa ‘do Jesu laini owo, sa wa ra.

3 mp Ma je k‘okan yin da yin ro,


Mase ro ti aye yin,
Gbogbo yiye t‘O mbere ni
Ki e sa mo aini yin
Cr Eyi to fun yin bi ‘mole lokan yin.

4 mp Eyin f eru npa, fare mu


Te sonu te si segbe
Bi e duro tit‘e o san
E ki yoo wa rara;
cr F‘elese ni, On ko wa f‘olododo.

5 mf Olorun goke l‘awo wa;


O nfi eje Re bebe,
cr Gbe ara le patapata,
Ma gbekele ohun mi,
F Jesu nikan l‘O le s‘elese l‘ore.

6 ff Angeli at‘awon mimo


Nkorin ‘yin Od‘agutan;
Gbohungbohun oruko Re
Si gba gbogbo orun kan,
Aleluya! elese le gberin na.
Amin.

203 8.6.8.6.4.
Israeli, yipada si Oluwa Olorun Re. Hos. 14:1.

1 mp Pada, asako s'ile re,


Baba re l‘o npe o,
Mase alarinkiri mo,
N‘n‘ese at‘osi re;
pp Pada; pada.

2 mp Pada, asako s‘ile re,


Jesu l‘O sa npe o,
cr Emi pelu Ijo si npe,
Yara, sa asala;
pp Pada, pada.
3 mp Pada, asako s‘ile re;
cr Were ni, b‘o ba pe,
mf Ko si ‘dariji n‘iboji;
Ojo anu kuru;
pp Pada, pada.
Amin.

204 L.M.
E wa nitori ohun gbogbo fetan.
Lk. 14:17.

1 f E lese, gba ‘hinrere gbo!


Wa si ase Oluwa mi,
Gbo, k‘o si m‘ojo ore re,
Ohun gbogbo set an, ma bo!

2 f Baba mura tan lati gba


Awon ‘mo Re t‘o pada wa;
Olugbala re mura tan,
O na ‘wo ogbe Re si O.

3 Emi ife Re mura tan


Lati m‘okan lile kuro,
Lati feje na s‘eleri,
K‘a we O, k‘a so o d‘omo.

4 f Awon angeli mura tan,


Lati y‘ayo ibukun re;
Won y‘o fi duru korin ‘yin
Ore-efe irapada.

5 f Baba, Omo, Emi Mimo


Mura pelu om‘ogun Re
cr Gbogbo orun y‘o si ho pe,
Oku ye, a ri eni nu!
Amin.
205 7.7.7.D.
Oluwa-odo Re ni mo sapamo si. OD. 143:9.

1 mp E mi are ti nsako
Kuro li arin ayo,
cr Wo Jesu t‘a kan mo 'gi,
Sa lo s‘ibi ogbe Re:
Ri n‘nu eje ‘wenuno,
cr Dide si iwa-mimo.

2 mf N‘nu Kristi l‘alafia wa


Alafia t‘a ko le so;
‘Rora Ren‘itura re
Iku Re ni iye re,
Dide nipa ‘rele Re,
Ohun gbogbo mbe n‘nu Kristi.

3 mf Gba eri otito gbo,


Eyin t‘a fi Jesu fun!
Eyin si le kun fayo,
K‘e m‘adun orun l‘aye,
Ki igbe aye yin je
Ti ife t‘o kun f‘ogo.

4 f Eyi l‘ alafia na,


Ta pese fun gbogb‘ eda,
Ileri Olorun ni,
Ebun Re ran araye,
Gba ‘bukun yi ninu
Krist Nisiyi ati laelae.
Amin.

206 12.9.12.9.&Ref.
Nigbati o ba wo o, yio ye. Num. 21:8.

1 mp Iye wa ni wiwo
Eni t‘a kan mo ‘gi,
Iye wa nisisiyi fun o;
Nje wo O elese k‘o le ri ‘gbala
Wo Eni t‘a kan mo ‘gi fun o
ff Wo! wo! wo, k‘o ye,
f Iye wa ni wiwo, Eni t‘a kan mo ‘gi
Iye wa nisisiyi funo.

2 mp Kini On se wa bi eleru ese


Ba ko ba gb‘ebi re ru Jesu!
Eje ‘wenumo ha se ti iha Re san,
Bi ‘ku Re ko ba san gbese re?

3 p Ki‘ s‘ekun ‘piwada ati t‘adura re,


pp Eje na lo s‘etutu f‘okan,
cr Gbe eru ese re lo si odo Eni
Ti o ti ta eje na sile.

4 mf Ma siyemeji s‘ohun ti Olorun wi


Ko s‘ohun to ku lati se mo
F Ati pe Oun yio wa nikeyin aye,
Y‘o si s‘ase pari ise Re

5 ff Nje wa fayo gba iye ainipekun


mf Ni OWO Jesu ti fi fun ni;
mp Si mo daju pe iwo ko le ku laelae
Gbati Jesu ododo re wa.
Amin.

207 11.11.11.7. & Ref


Filipi SO fun pe, ― Wa wo O ‖.
Jn. 1:46.

1 mf Ipe ihinrere na ni yi, Wa wo,


Fun gbogbo orile ede ni,
Wa wo, Jesu mu igbala ofe wa,
Wa wo, Ohun ti O se fun mi.
F Wa wo, wa wo,
Ohun ti O se fun mi
cr O r‘okan mi n‘nu ese
O si we mi mo toto,
mf Eyi ni O se fun mi.

2 Oun ki yoo tan o je laelae, wa wo,


Y‘o gba o ninu wahala re gbogbo,
cr O nduro lati tewo gba o wa wo
Gbogb‘ ohun to se fun mi.

3 f Wa f‘Olugbala se igbekele re,


Tete sa si abe abo Re, wa wo
mp Ninu anu Re ni k‘o ma gbe,wa wo
Ohun ti O se fun mi.
Amin.

208 11.9.11.9. & Ref.


Nigbati o ba wo o, Yio ye. Num. 21:8.

1 mf Oluwa ran mi ni ‘se, Aleluya!


IWO ni uno je ise na fun;
A ko s‘inu Oro Re, Aleluya!
P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye.
ff Wo, k‘o ye, Arakunrin,
Wo Jesu ki o si ye,
mf A ko s‘inu Oro Re, Aleluya!
P‘eni t‘o ba wo Jesu y‘o ye.

2 mf A ran mi n‘ise ayo, Aleluya!


Uno j‘isena fun o ore mi;
cr Ise lat‘ oke wa ni; Aleluya!
mp Jesu SO, mo mo pe oto ni.

3 mf A n‘owo iye si O, Aleluya!


f A o fi ‘ye ailopin fun O;
T‘o ba wo Jesu nikan, Aleluya!
ff Wo o, On nikan l‘o le gbala. .
Amin.
209 7.6.7.6.D. & Ref.
Eje Jesu Kristi Omo Re ni nwe wa
nu kuro ninu ese gbogbo. I Jn. 1:7.

1 mf I sun ‘wenumo kan mbe


cr Lati oke Kalfari,
Oluwa si isun na
mf Fun gbogbo elese,
Nisiyi ohun re npe
Lati SO d‘ominira
f E wa fun iwenumo
cr Nibi ite-anu.
p Isun ti nsan ni Kalfari
Isun Kalfari na nsan
cr Lofe lo nsan, fun gbogbo
wani
Isun Kalfari na nsan.

2 mp Bi eru ese npao


Ti are si mu o,
Agbara mbe n‘isun na,
Wa we n‘nu isun na.
mf Iwosan mbe ninu re
Pelu iwenumo,
Omi anu nsan titi
Lat‘ oke Kalfari.

3 mf Orisun iye n‘ise,


Lofe l‘o nsan fun wa,
mp Bere, we ki o si mo,
Si gba omnira re,
F Gba Kristi l‘Oluwa re
Y‘o SO o di kanga
Alafia at‘ayo
Y‘o ma san ninu re.
Amin.

210 7.7.8.7.6.7.8.7. & Ref.


Nitori Olorun fe araye tobe ge,
ti o fi Ome bibi Re kan soso fun ni Jn. 3:16.

1 mf Agogoihinrere
Nlu lat‘ilu de ilu,
‘Bukun ati ‘gbala ofe
Ni won fun o at‘emi,
mp Olorun f‘ araye
T‘o fi Omo Re fun wa;
F F‘enikeni ti o gb‘A gbo
Y‘o ni ‘ye ainipekun.
F ‘Hinrere b‘o ti ndun
Lati ilu de ilu,
‘Hinrere l‘ofe ni,
‘Hinrere to n‘ibukun.

2 mf Agogo ihinrere
Npe wa si ase nla na,
F Jo, ma ko ipe Oluwa,
Ma si ko ‘pe or‘ofe,
mp Akara ‘ye l‘Emi,
Je n‘nu re okan ebi,
p B‘ese re pon bi ododo
mf ‘Won y‘o funfun bi owu.

3 Agogo na nma nkilo


B‘o ti nlu lojojumo
Ni p‘ohun to le de b‘awon
To f akoko jafara
F S‘asala f‘emi re,
Ma duro ni petele
mf Mase b‘oju wo eyin re,
Ki egbe ma se ba o.

4 f Ayo ni agogo na,


ff Fi nlu kakiri aye,
NSO nipa ti idariji
Ti Jesu y‘o fi fun wa
‘Hinrere t‘ayo nla
L‘o mu wa fun gbogb‘ eniyan,
F Fun ol‘abi Olugbala
Krist‘ Oluwa at‘Oba.
Amin.

211 S.M.&Rcf.
Eniti o ba TO mi wa,
Emi k i yio taanu bi o ti wu ki o ri Jn 6:17.

1 f Oluwa mo gb'ohun Re,


Ti npe mi wa ‘do Re.
Fun ‘wenumo n‘nu eje Re
To san ni Kalfari
mf Mo mbo Oluwa,
Mo mbo sodo Re
cr We mi ninu eje Re
To nsan ni Kalfari.

2 mp Bi mo mbo n‘nu ailera,


‘Ranlowo Re daju,
‘Wo mu ailera mi kuro,
Emi si di mimo.
3 mf Jesu li Ope mi
Si ‘gbagbo on ife,
Si ‘reti ati eje Re
T‘o nsan ni Kalfari.

4 p A! eje etutu
pp A! ore ‘rapada
cr A! ebun Kristi Oluwa wa
mf L‘okun, ododo wa.
Amin.

212 L.M.
Nje gbogbo eniti ongbe ngbe, e wa si ibi omi. Isa. 55:1.

1 mf Gbogbo eni t‘ongbe ngbe, wa!


F Olorun npe gbogb‘ elese;
cr Ran anu on ‘gbala lofe;
Ra or‘-ofe ihinrere.

2 mp Wa s‘ibi omi iye, wa!


Elese, je ‘pe Eleda,
Pada, asako, bo wa ‘le,
Ofeni ore mi fun yin!

3 mf Wo apatati nsun jade!


Isun ‘marale nsan fun o,
Eyin ti eru ese npa,
E wa, laimu owo L‘OWO.

4 mf Ko s‘iparo t‘e le mu wa,


cr E f ini yin gbogbo seyin,
f F‘igboya gb‘ebun Olorun,
Ni idariji n‘nu Jesu.
Amin.

213 7.7.7.7.D.
E wa SODO mi gbogbo enyin ti nsise,
ti a si di eru wuwo le lori Mat. 11:28.

1 mf Wa, alaare, elese,


cr Eyin t‘eru ese npa;
f Jesu np‘asako wa ‘le,
Wa ‘fiji lod‘ Olorun!
di Eyin ti ese te ba,
Je ipe Olugbala Wa
Wa un o fun yin ni ‘simi
Wa, uno gba gbogbo yin la.

2 mf Jesu t‘o kun fun oto


cr Awa gba oro Re gbo,
Fi oto anu Re han,
Ko eru ese wa LO;
Awa fe gbokanle O,
K‘a k‘aniyan wa le O
K‘a sa s‘abe anu Re,
K‘ar‘isimi l‘odo Re

3 p Ibanuje te wa ba,
pp Ese wa wo wa lorun,
cr Aigbagbo bo wa mole
Pelu ‘binu Olorun;
mf Wo! a to wa fun ‘rora,
‘Wo Oloto Olore,
Da emi are wan‘de,
Fi ‘dariji fokan wa.
Amin.

214 9.9.9.6.D.
E wa sodo mi gbogbo enyin ti nsise,
ti a si di eru wuwo le lori Emi
o si fi isimi fun nyin. Mat. 11:28. '

1 mf W a s‘odo Jesu, mase duro;


L‘oro Re l‘o ti fona han wa,
Oduro li arin wa loni,
Onwi pele pe, wa!
cr Ipade wa yio je ayo,
Gb‘okan wa ba bo L‘OWO ese.
T‘a o si wa pelu Re,
Jesu, N‘ile ayeraye!

2 f Jek‘omode wa! E gb‘ohun Re;


Jek‘okan gbogbo kun fun ayo,
K‘a si yan Jesu l‘ayanfe wa,
Ema duro, e wa.
3
mf Ranti p‘O wa pelu wa loni,
F‘ eti s‘ofin Re, k‘o si pamo;
cr Gbo b‘ohun Re ti nwi pele pe
Eyin omo Mi wa. .
Amin.
215 9.8.10.8. & Ref.
Bi enikeni ba nsin mi, ki o ma to
mi lehin Jn. 12:26.

1 f T ani y‘o koko tele Jesu?


Tani y‘o ko gb‘agbelebu?
mf Enikan se tan, enikan nlora
f tani y‘o de ade na?
ff Tani y‘o ko de ade na?
Tani y‘o koko tele Jesu?
Tani y‘o koko tele Jesu n‘siyi?
Tele de opin?

2 mf Tani y‘o koko tele Jesu?


Wa wole leba ese Re,
Tani y‘o ko ko aniyan re wa?
cr Lese Baba n‘ite - anu.

3 mf Tani y‘o koko tele Jesu?


Tani y‘o ko ‘yin Oko Re?
cr Tani nfe ba won korin ‘rapada
f Orin Aleluya loke.
Amin.

216 12.11.12.11. & Ref.


E ba Olorun laja. II Kor. 5:20.

1 mp Gbo elese bi Olorun re ti npe o,


cr Ti O si nkilo pelu ohun anu;
Feti s‘ohun Re ki ‘dajo ma ba O,
Mf ―Ikore nkoja lo, erun y‘o pari‖
―Ikore nkoja lo, erun y‘o pari,‘
―Ikore nkoja lo, erun y‘o pari.‘

2 mf Oluwa nke pe k‘o kuro l‘ona 'parun,


Ipe anu Re ni eyi je fun O;
Yara n‘siyi, bo s‘abe abo ife Re.
―Ikore nkoja lo, erun y‘o pari‖

3 cr K‘ibanuje at‘ eru ma ba je ‘pin re,


Mase ko ipe anu to nko si o,
mf Mura, elese gbon, k‘o si gba ipe na,
―Ikore nkoja lo, erun y‘o pari‖

4 Laipe, Jehofa y‘o wa nin‘ agbara re


Lati fenikokan b‘ise re ti ri:
Ara, mura f‘ojo na, iku ko d‘ojo
―Ikore nkoja lo, erun y‘o pari‖

5 mp Oluwa y‘o pe o siwaju ‘te dajo;


Nitorina f‘Olugbala s‘ ore re,
cr Omo fi okan re fun, k‘o si juba Re
―Kore Re nkoja lp, erun yo pari‖
Amin.

217 7.10.7.7.& Ref.


Nitori ailabawon li ebun ati ipe Olorun. Rom. 11:29.

1 mf ‘Gbala-ofe s‘owon bi,


F‘enit‘o ba fe, f‘eni t‘o ba fe?
Tal‘ o nfe ayeraye?
Eni t‘o ba fe le wa.
mp Enit‘obafe lewa (‘do Jesu)
Eni t‘o ba fe le wa (‘do Jesu)
F ‘Gbala-ofe wa f‘enikeni
Eni t‘o ba fe le wa (le wa.)

2 f Olorun fe gbogbo wa,


Eni t‘o ba fe, eni t‘o ba fe
Bi a ba gba ipe Re
Enit‘obafele wa.

3 f Sibesibe O npe wa,


Eni t‘o ba fe, eni t‘o ba fe
Ife mimo Re npe wa,
Eni t‘o ba fe le wa.
Amin

218 8.7.8.7.4.7.
Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Isreali,
e wa mi, enyin o si ye. Amo. 5:4.

1 mf Elese o ha gan ise


T‘afanu ran lat‘ oke;
Ohun jeje l‘o fi ranse
Oro Re kun fun ife;
Te ti lele,
Ise Re kun fun ife

2 f Gbo awon ojise rere,


Won nj‘ise Oba Sion;
―Idariji fun elese
L‘ofe l‘oruko Jesu‖
Cr Botipoto.
p ‘Dariji l‘oruko Re.

3 f F‘okan itanje at‘eru


Won mu ‘bale aya wa,
Won wa fi ise itunu,
Le omije yin kuro;
p Ojise ‘re,
pp Nu omije nu kuro.

4 mf Tani ti gba ihin wa gbo?


Tani gb‘oro ayo na?
T‘o gba ihin ‘dariji mu
Ti Oluwa na si yin?
E ha le gan
Ore anu Oluwa.
Amin.

219 L.M.
Bi enyin o ba gbo ohun re,
e ma se aya nyin le. OD. 95:7,8.

1 f M ura, elese, lati gbon,


Ma duro de ojo ola;
Niwon b‘o ti kegan ogbon,
Be l‘o si soro lati ri.

2 mf Mura lati bere anu,


Ma duro de ojo Ola;
Ki igba re o ma batan,
p Ki ojo ale yi to tan.

3 f Mura, elese, k‘o pada,


Ma duro de ojo ola;
p Nitori k‘ egun ma ba o,
K‘ ojo ola k‘o to bere.

4 f Mura lati gba ibukun,


Ma duro de ojo ola;
p Ki fitila re ma ba ku,
K‘ise rere re to bere

5 f Oluwa, y‘elese pada,


Ji kuro ninu were re;
Ma je k‘o tapa s‘imo Re,
p K‘o ma fegbe re se ‘lora.
Amin.

220 CM.
Eje Jesu Kristi Omo re ni n we
wanu kuro ninu ese wa gbogbo. I Jn. 1:7.

1 mf Nihinyi n‘isimi gbe wa,


Niha re t‘ eje nsan;
Eyi nikan n‘ireti mi,
p Pe Jesu ku fun mi.

2 Olugbala, Olorun mi,


Orisun f‘ese mi;
Ma f‘eje Re won mi titi,
K‘ emi le di mimo.

3 mp We mi, si se mi ni Tire,
We mi, si je temi;
We mi, k‘ is‘ ese mi nikan,
Owo at‘ okan mi.
4 f Ma sise l‘okan mi, Jesu,
Titi ‘gbagbo y‘o pin;
Tit‘ ireti y‘o fi dopin,
T‘ okan mi y‘o simi.
Amin

221 7.7.7.7.
E wa Oluwa nigbati e le ri i,
Epe E nigbatio wa nitosi. Isa. 55:6.

i f O jo nsure, o nkoja;
p Iku nsure, o de tan;
cr Elese nsawada ni!
p Ojo at‘ iku nwo o

2 Emi nsure, t‘o ba pin.


cr ‘ Wo ko le pada mo lae;
'WOO bo s‘ainipekun;
Ko ha ye k‘ iwo ronu?'

3 f Olorun ngbo, gbadura,


Ki igba re to.koja;
K‘ Ite ‘dajo Re to de,
K‘ anu to tan k‘ esan de.

4 mf Mura giri, iku mbo,


B‘o ba duro, o segbe;
di Ma sun mo, dide, sare;
" Olugbala nreti re.
Amin.

222 S.M.
E jeki a se lala lati WO inu isimi na. Heb. 4:11.

1 mf N ibo n‘isimi wa
‘Simi f okan are?
Lasan l‘a wa s‘opin okun,
Ati s‘ opin ile.

2 Aye ko le fun ni
N‘isimi ti a nfe;
K‘a le pe titi laye ko!
p K‘a si tete ku ko!

3 Aye kan mbe loke


T‘o jinna s‘ aye yi,
Won ko nsiro odun nibe;
Ife ni aye na!
4 p Iku mbe, apa re
Kawo‘emi wa yi;
pp B‘ irora kikoro ti to
cr Ninu iku keji!

5 f Olorun jo ko wa
p K‘a sa fun iku yi;
K‘a ma ba le wa lodo Re,
K‘a si segbe laelae.

6 Nihin l‘ebe wa mo!


Aye ife pipe,
Ati isimi ailopin
Wa ninu Re nikan.
Aminl

223 7.7.7.7.D.
............. Nitori kini enyin o se ku,
ile Israel? Esek. 18:31.

1 mf K ini Jesu ‘ba tun


Ju b‘O ti ku fun o lo?
O ta eje Re sile
Fun ‘repo ‘wo Qlorun.
di E se t‘iwo nse Jesu?
Ese ti o fe segbe?
Ife Ret‘O nfi fa o,
Asan l‘o je fun o bi?

2 p Elese, e yipada,
cr Olorun ti pinnu pe,
On y‘o so yin di aye,
On y‘o gba gbogbo eniyan,
B‘ iku yin je ife Re
O ha le pe yin s‘ iye?
Di F‘eti s‘ohun Re t‘o ni
p Ese ti e fi segbe?

3 p EIese, e yipada,
cr Olorun mbe nitosi,
Olugbala re duro,
O na ‘wo alafia,
mp Eyin ko ni to Mi wa!
Emi t‘o nfi ‘ye fun ‘ni!
Mase ro pe nko n‘ife,
p Ese ti e fi segbe!

4 mf Iwo y‘o siyemeji


Si ife Olorun re?
‘Wo ki ha ni ‘gbagbo
S‘ileri at‘oro Re?
Wo Jesu t‘o jiyare!
Ni ‘gbagbo si iya Re
di Gb‘ohun eje Re nke pe,
p Ese tie fi segbe!
Amin.

224 S.M.
Ema gba ara nyin niyanju lojojumo
nigbati a npe loni.
Heb. 3:13.

1 mf T ire l‘ola Baba,


O wa n‘ikawo Re;
B‘ojum‘ Ola si mo ba ni,
Nipa ase Re ni.

2 Akoko yi nfo lo,


O ngbe emi wa lo,
Oluwa, mu ‘ranse Re gbon,
Ki won le wa fun O.

3 mp Akoko to nlo yi,


L‘ayeraye ro mo;
Fi agbara Re Oluwa,
Ji agba at‘ewe.

4 On kan l‘aba ma du;


T‘aba ma lepa re;
Pe k‘igba ‘bewo wa ma LO,
Lai tun pada mo.

5 Je ka sa to Jesu,
K‘a si sure tete;
K‘emi wa ma ba ku k‘o ri
p S‘okun biribiri.
Amin.

225 C.M.
Gbogbo eniti ongbe ngbe, e
wa sibi omi Isa. 55:1.

1 E yin t‘ ongbe ngbe, e wa mu


Omi iye ti nsan;
Lati orisun ti Jesu
Laisanwo l ‘ awa nbu.

2 p Wo! b‘o ti pe to t‘e ti nmu


Ninu kanga eke
T‘e nl‘agbara at‘ogun yin
cr Ninu nkan t‘o nsegbe.

3 Jesu wipe, isura Mi,


Ko lopin titi lae
Yio filera laelae fun
Awon t‘o gbo Tire
Amin.

226 S.M.
Emi ati lyawo wipe, Ma bo wa.
Ifi. 22:17

1 mp E mi okan wa npe,
O np‘elese k‘o wa;
‘Yawo, Ijo Krisiti si npe
K‘awon omo re wa.

2 f Je k‘eni t‘o gbo, wi


F‘awon t‘o yika wa:
Eni t‘ongbe ododo ngbe
K‘o wa sodo Kristi.

3 Loto; eni t‘o fe,


Je ki o wa l‘ofe,
K‘o mu omi iye l‘ofe
Jesu l‘o pe k‘o wa.

4 f Gbo, bi Jesu ti npe,


ff Wipe, mo mbo kankan
Beni Jesu mo nreti Re,
Ma bo Olugbala.
Amin

227 L.M.&Ref.
E o si mo otito, otito yio si SO nyin
di ominira. Jn. 8:32.

1 Bi Krist‘ ti da okan mi nde,


Aye mi ti dabi orun,
Larin ‘banuje at‘aro
Ayo ni lati mo Jesu,
Aleluya! ayo l‘o je
Pe, mo ti ri ‘dariji gba,
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s‘ewu, Jesu wa nibe

2 Mo ti ro pe orun jina
Sugbpn nigbati Jesu de
L‘orun ti de ‘nu okan mi,
Nibe ni y‘o si wa titi.
3 Nibo l‘a ko le gbe l‘aye
L‘o r‘oke tabi petele,
L‘ahere tabi agbala,
Ko s‘ewu, Jesu wa nibe
Amin.

228 9.8.9.7.& Rel .


Nitori Omo mi yi ti ku, o si
tun ye; O ti nu, a si ri i. Lk. 15:24

1 Lekan, mo j‘elese, sugbon mo


Ti gba ‘dariji l‘od‘Oluwa,
L‘ofe l‘a fifun mi, mo si ri
Pe O npa oro Re mo.
Oko titun t‘a ko sile n‘n‘ogo
T‘emi ni toto, t‘emi
Awon angeli mimo nko ‘rin na
Elese kan wa le
Tor‘oko titun kan ti a ko n‘n‘ ogo
T‘emi ni, toto temi,
Leyin ‘dariji ese, orun ni mo nlo
Nko tun sako mo.

2 Mo fi ‘rele kunle l‘ese Krist‘


Mo si mberu ‘binu Olorun,
Nigbat‘ a si orun, ti mo ri
P‘a ko ‘ruko mi sile;

3 Or‘-ofe nikan l‘o gba mi la,


Ayo ki l‘o de si okan mi
A ti dariji mi mo si mo
P‘eJe Krist‘ mu mi pe.
Amin.

229 12.12.12.13. & Ref.


Nigbati awa je elese. Kristi ku fun wa. Rom. 5:8.

1 Lekan, oju mi ti fo s‘ogo Oluwa


L‘ekan, eti mi ti di s‘ohun oro Re
L‘ekan, mo te ade egun mo li ori,
Sugbon O ti dariji mi, ko tun si nkan mo.
Ko si nkan mo, beni, ko si nkan mo
O ti gbo adura mi, ko si nkan
Ko si nkan mo, beni ko si nkan mo
O ti bo gbogb‘ ese mi, ko tun si nkan.

2 Lekan ri, mo fe aye ati ogo re


Adun aye yi ti de mi ni igbekun
Sugbon On de n‘jo kan l‘ona ti nko le SO
O fi eje Re bo ese mi, ko si nkan mo

3 Ohun rere ni lati wa l‘odo Jesu


‘Gbati ‘danwo de, ti oju mi si sokun,
Ki nsa ri owo ife Re li ori mi
Ki nsi gbo ohun jeje Re wipe: ko si nkan.
Amin.

230 9.1.9.1. & Ref


A dari ese re ti o po ji o
Lk. 7:47.

1 mf B i a ba ko ese mi sile,
Ki nsi ri b‘o ti po to,
Ibanuje mi yo ti po to,
Sugbpn Baba ti we mi,
cr O f eje Re ‘yebiye we mi mo
p O ko ese milo,
cr Nisisiyi mo di t‘Oluwa laelae
On na si jetemi.

2 mf Bi mo ba le wo yika kiri
Lati wa ese mi ri,
Nko le ri okan soso n‘nu re
Mo ti gba idariji.

3 f Baba ko ranti ese mi mo,


Won ti lo s‘okun ‘gbagbe.
Uno korin iyin s‘oruko Re
O sa ti dariji mi.
Amin

231 9.9.9.8 & Ref


A wa ti fi gbogbo re sile, awa si nto O lehin Mat. 19:27.

1 mf Gbogb‘ ohun t‘o nfa mi, mo fi ‘le,


Nihin ni Kenan‘ mo ri ayo;
F Alafia, ‘bukun ‘yebiye,
cr ‘Tori mo ngbe Kenani n‘siyi.
F Mo ngbe Kenani nisisiyi.

2 f Mo ngbe lail‘ewu nko je beru,


Olugbala mi wa nitosi,
‘Gba mo ba pe, y‘o gbadura mi
‘Tori mo ngbe Kenani n‘siyi.

3 mj Mo mu omi kanga alaigbe,


Ni Kenani ibugbe ife mi!
F Emi o so fun elomiran
Cr Pe emi ngbe n‘ile Kenani
4 ff Iyin ailopin ni mo mu wa
Fun Jesu, Oba Irapapda;
Mf Em‘ o korin opo anu Re,
‗Tori mo ngbe Kenani n‘ siyi
Amin.

232 7.7.7.
Jeki nwon wipe, da awon eniyan re si,
Oluwa, ma si se fi ini re fun egan.
Joe. 2:17.
1 p Jesu, l‘ojo anu yi,
Ki akoko to koja,
A wole ni ekun wa.

2 p Oluwa m‘ekun gbon wa,


Fi eru kun aya wa,
Ki ojo iku to de.

3 Tu emi Re s‘okan wa,


L‘enu-ona Re l‘a nke;
K‘ ilekun anu to se.

4 pp ‘Tori ‘waya - ija Re,


‘Tori ogun - eje Re.
‘Tori iku Re fun wa.

5 p ‘Tor‘ ekun kikoro Re,


Lori Jerusalemu,
Majek‘agan ife Re

6 IWO Onidajo wa,


‘Gbati oju wa ba ri O,
Fun wa n‘ipo l‘odo Re*

7 mf Ife Re l‘a simi le,


N‘ile wa l‘oke T ao mo
B‘ife na ti tobi to.
Amin.

233 C.M.
Nitorina ejeki a wa si ibi ite ore-ofe pelu igboya ,
Heb. 4:16.

1 mf O kan mi, sunmo ‘te anu,


N‘ ibi Jesu ngb‘ebe,
F‘ irele wole lese Re.
A ko segbe n‘ be

2 mp Ileri Re ni ebe mi,


Eyi ni mo mu wa
IWO npe okan t'eru npa
Bi emi Oluwa.

3 p Eru ese WO mi l‘or un,


Esu nse mi n‘ise;
Ogun l‘ode eru ninu
Mo wa isimi mi.

4 mf se apata at‘ asami,


Ki nfi O se abo;
Ki nd‘oju ti Olufisun,
Ki nso pe, ―Kristi ku‖

5 mf Ife iyanu! IWO ku,


cr IWO ru itiju
cr Ki elese b‘iru emi
Le be l‘oruko Re.
Amin.

234 7.7.7.7.
Olorun san fun mi emi elese
Lk. 18:13.

1 mp Elese: mo nfe ‘bukun


Onde: mo nfe ominira
Alare: mo nfe ‘simi;
p ‗Olorun, sanu fun mi. ‖

2 mp Ire kan, emi ko ni,


Ese sa l‘o yi mi ka,
Eyi nikan l‘ebe mi
p ―Olorun, sanu fun mi. ‖

3 mp Irobinuje Okan!
Nko gbodo gb‘oju s‘oke;
IWO sa mo edun mi;
p ―Qlorun, sanu fun mi.‖

4 cr Okan ese mi yi nfe


Sa wa simi laya Re,
Lat‘ oni, mo di ti Re
p ―Olorun, sanu fun mi.‖

5 mj Enikan mbe lor‘ Ite.


Ninu Re nikan soso
F N‘ieti at' ebe mi
p ―Olorun, sanu fun mi‖

6 mf On o gba oran mi ro,


On ni alagbawi mi,
Nitori Tire nikan,
p ―Olorun', sanu fun mi‘
Amin

235 S.M.
Bojuwo mi, ki O si sanu fun mi. OD. 119:132.

1 p J esu, jo ranti mi
Ko si w‘ese mi nu
cr Gba mi low‘ese ‘binibi,
Si we okan mi mo.

2 p Jesu, jo ranti mi,


Mo kun fun aniyan,
cr Ki n‘ je ‘ranse t‘o n ife Re
Ki njogun ‘simi Re

3 mf Jesu, jo ranti mi,


L‘arin ‘gbona ogun
N‘nu ‘rora on banuje mi.
cr Je ‘lera, Iye mi.

4 p Jesu, jo ranti mi,


Ma je ki nsako lo
Cr N‘nu ‘damu on okun aye
F‘ ona orun han mi.

5 mf Jesu, jo ranti mi,


cr Gbat‘iji ru s‘oke
f ‘Gbati ota wa nitosi,
Jesu, jo sun mo mi.

6 Jesu, jo ranti mi,


‘Gba gbogbo re koja.
Ki nle r‘ogo ainipekun,
Ki nsi le ba O yo.
Amin

236 C.M.
Olorun sanu fun mi, emi elese. Lk. 18:13.

1 mp Oluwa, ma m‘oju kuro


L‘odo mi t‘o nyi ‗le,
Ti nsokun ese aye mi,
Niwaju ite Re

2 mp Ilekun kan si f‘elese.


Ti nsokun ese won,
Mase se Mekun na mo mi,
Gba mi s‘ile, Baba.

3 mp Iwo mo, ki nto jewo re;


Ise mi l‘aye mi,
At‘ iwa mi nisisiyi,
Gbogbo re ni ‘WO mo.

4 mf Oluwa, mo de ‘bi ‘te Re


Nibiti anu po!
Mo fe ‘dariji ese mi,
K‘o mu okan mi da.

5 pp Oluwa, ko ye k‘emi so
Ohun ti mba bere,
O ti mo k‘emi t‘ o bere
Ohun ti emi fe.

6 Oluwa mo toro anu,


Eyiyi l‘ opin na;
Oluwa, anu l‘o ye mi
Je ki nr‘ anu Re gba.
Amin.

237 8.8.8.D.
Sa wo o, awa to O wa nitori IWO li
Oluwa Olorun wa. Jer. 3:22.

1 mp O su mi lati ma sako,
O toge, uno wa Olorun;
Mo teriba fun opa Re,
Fun O, mo ns‘ofo n‘nu ‘reti,
cr Mo n‘ Alagbawi kan l‘oke,
Ore niwaju ‘te ife

2 mf A! Jesu t‘o kun f or‘-ofe


Ju bi mo ti kun fun ese,
Lekan si mo tun nwo ‘ju Re
N‘apa Re si gba mi mo ‘ra
L‘ofe wo faseyin mi san;
Fe em‘ alaigbagbo sibe

3 mp ‘Wo m‘ona lati pe mi bo,


Lati gb‘ eni t‘o subu ro;
A! tor‘ anu at‘oto Re
Dariji, ma je ki n‘se mo,
cr Tun ibaje okan mi se,
Ko si se n‘ile adura

4 mp A! fun mi ni kan riro


Ti y‘o ma wa riri f‘ese,
Fun mi ni iberu f‘ese
Mu ko ta gbongbo ninu mi;
Ki nle beru agbara Re,
Ki nma tun d‘ese si O mo.
Amin

238 6.4.6.4.6.6.6.4.
Nitori oruko Re, dari ese miji.
OD. 25:11.

1 Ki ‘sel‘aini ‘reti
Ni mo to ‘wa
Ki‘se laini‘gbagbo
Ni mo kunle,
Ese ti g‘ ori mi
Eyi sa l‘ebe mi,
cr Eyi sa l‘ebe mi,
Jesu ti ku.

2 p A! Ese ni ipo ju,


O pon koka
Ada le, ada le
Ni mond‘ese;
Ese aiferan Re
Ese aigba O gbo,
Ese aigbo O gbo,
Ese nlanla.

3 mp Oluwa, mo jewo
Ese nla mi,
' O mo bi mo ti ri,
Bi mo ti wa;
p JO, we ese mi nu,
K‘okan mi mo loni,
K‘okan mi mo loni,
Ki ndi mimo.

4 mf Olododo ni O,
O ndariji
L‘ese agbelebu
Ni mo wole;
p Jek‘eje iwenu
Eje od‘agutan,
Eje od‘agutan,
We okan mi.

5 cr ‘Gbana alafia
Y‘o d‘okan jni,
‘Gbana uno ba 0 rin,
Ore airi;
Ore airi;
mf Em‘ o f‘ara ti O;
JO ma to mi S'ONA,
JO ma to mi S‘ONA,
Titi aye.
Amin.

239 8.8.8.6,
Enikeni ti o to mi wa,
Emi kiyio ta a nu,
bi o ti wu ko ri. Jn. 6:37.

1 mp B i mo ti ri, lai s‘awawi,


Sugbon nitori eje Re
B‘ o si ti pe mi pe ki nwa;
p Olugbala, mo de.

2 Bi mo ti ri, laiduro pe,


Mo fe k‘ okan mi mo toto,
S‘odo Re to le we mi mo,
p Olugbala, mo de.

3 Bi mo ti ri, b‘o tile je


Ija l‘ode, ija ninu
p Eru l‘ode, eru ninu,
Olugbala, mo de.

4 di Bi mo ti ri, osi are;


Mo si nwa imularada,
cr IWO le s‘awotan mi,
p Olugbala, mo de.

5 Bi mo ti ri ‘WO o gba mi,


‘ Wo o gba mi, t‘owo t‘ese;
mf ‘Tori mo gba ‘leri Re gbo;
p Olugbala, mo de.

6 mf Bi mo ti ri ife Tire,
L‘o sete mi patapata,
Mo di Tire, Tire nikan;
p Olugbala, mo de.

7 cr Bi mo ti ri, n‘nu fe nla ni


T‘o fi titobi Re han mi;
Nihin yi ati ni oke;
p Olugbala, mo de.
Amin.

240 7.7.7.7.
E mase je ki okan nyin daru.
Jn. 14:1.

1 mp I bu ife, o le je
Pe a p‘anu mo fun mi,
Olorun mi ha le da
Binu ro fun elese?

2 di Mo ti mba ri‘nu je ti pe!


Mo ti nbi ninu ti pe!
Mo di ‘ti si ife Re,
Mo f op‘ ese bi ninu.

3 mp Ase‘femi po toyi?
Bi Alagbawi mi wo;
Wadi re lodo Jesu,
Niwaju ‘te or‘-ofe

4 Nibe l‘O f‘ogbe OWO


P Ati t‘ese Re han mi,
Ife l‘Olorun, mo mo,
Cr Jesu ye, O si fe mi.

5 Jesu f‘ife Re dahun


N‘tori ife n‘iwa Re,
Mo wole li ese Re,
‘WO k‘ yo ha dariji mi?

6 Fi oju anu wo mi,


Si pe Okan mi wa ‘le,
S‘okan lile di riro,
K‘oju Re tu mi ninu.
Amin

241 7.6.7.6.D. & Ref.


Gbo adura mi Oluwa, ki o sije
ki igbe mi ki o wa sodo Re.
OD. 102:1.

1 mf Olugbala, gb‘ohun mi
Gb‘ohun mi, gb‘ohun mi,
Mo wa s‘odo Re, gba mi,
p Nibi agbelebu di
Emi se sugbon Oku;
IWO ku, IWO ku,
Fi anu Re pa mi mo
Nibi agbelebu,
F Oluwa, jo gba mi,
Nki y‘o bi O ninu mo!
Alabukun, gba mi
Nibi agbelebu.
2 Ese mi po lapoju
Uno bebe, un o bebe!
IWO li Ona iye,
Nibi agbelebu,
Ore-ofe Re t‘a gba,
L‘ofeni! L‘ofeni;
F‘oju anu Re wo mi,
N‘ibi agbelebu.

3 f F‘eje mimo Re we mi,


Fi wemi! fi we mi!
Ri mi sinu ibu Re,
P N‘ibi agbelebu
‘Gbagbo l‘o le fun wa ni
Dariji Dariji
Mo f‘igba ro mo O
N‘ibi agbelebu.
Amin.

242 10.7.10.7. & Ref.


Fa mi, awa yo sare to O.
O.Sol. 1:4.

1 mp O luwa, emi sa ti gb‘ ohun Re


O nso ife Re simi,
Sugbon mo fe nde l‘ apa igbagbo
Ki nle tubo sun mo O,
Mf Fa mi mora, mora, Oluwa
Sib‘ agbelebu t‘O ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Sib‘ eje Re t‘on‘iye.

2 f Ya mi si mimo fun ise Tire,


Nipa ore-ofe Re,
Je ki nil okan igbagbo w‘ oke
K‘ ife mi'si je Tire,

3 f A! ayo mimo ti wakati kan


Ti mo lo nib‘ ite Re;
‘Gba mo ngb‘ adura si O, Olorun
Ti a soro bi ore

4 f Ijinle ife mbe ti nko le mo


‘Titi un"o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Titi uno fi de ‘simi
Amin
243
Lati wasu idasile fun awon
igbekun. Lk. 4:18.

1 mf Lati ‘nu ide ibanuje


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa gba ominira at‘ayo,
Jesu mo wa ‘do Re.
Alai san, emi nfe iwosan;
Alaini, SO mi di Oloro;
cr Elese. mo wa si odo Re;
Jesu, mo wa ‘do Re.

2 Ninu ‘tiju ati ofo mi Jesu mo de, Jesu mo de,


Mo wa jere nla n‘nu iku Re,
Jesu mo wa ‘do Re,
‘WO ni itunu fun ‘banuje;
‘WO n‘isimi fun gbogbo iji,
Orin dipo idanwo gbogbo,
Jesu mo wa ‘do Re.

3 cr Ninu rudurudu aye yi,


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa s‘abe ase anu Re,
Jesu mo wa‘do Re,
Mu mi kuro n‘nu ife ara,
Kuro ninu aye asan yi,
Ki nle wa fi iye fo g‘oke,
Jesu mo wa ‘do Re.

4 cr N‘nu eru iku at‘iboji


Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa s‘inu ayo ile mi,
Jesu mo wa ‘do Re,
Lati ‘nu iho iparun nla
Sinju alafia t‘ o jinle
Lati wa w‘ oju Re; ologo,
Jesu mo wa‘do Re.
Amin.

244 S.M.
Lehin igbati o ti ru ebo kan fun ese titi lae,
ojoko li OWO Otun Olorun. Heb. 10:12.

1 mf Gbogbo eje eran


T‘ a pa ni pepe Ju
cr Ko le fokan l‘ alafia,
Ko le we eri nu.
2 cr Krisiti Od‘agutan
Ko gbogb‘ ese wa LO:
Ebo t‘o n‘ iye lori
Ju eje eran LO

3 f Mo fe fi igbugbo
Gb‘owo le O lori,
Ki nsi f‘ ironupiwada
Se ‘jewe ese mi.

4 p Mo fi oju okan
Wo O lori igi
Nigbat‘ O ru ese aye
Ati temi pelu.

5 Awa yo ni ‘gbagbo
Pe, egun ti kuro
A sope fun Od‘agutan,
A gbekele ‘ fe Re
Amin.

245 C.M.
Eyipada kuro ninu ona buburu nyin,
nitori kini enyin o se ku. Esek. 33:11.

1 mf Wa, Oluwa Olusegun,


Fi ipa Re han wa;
Si fi agbara oro Re
FO okan lile wa.

2 cr Gbogbo wa ‘ba t‘oni bere


Si kanu ‘sise wa,
K‘ a peyinda si ese wa,
K‘ a wa Olugbala!

3 mp Jek‘ a mo O k‘a mo ‘ra wa


Lojo anu wa yi;
Yi wa pada k‘a ba le ye,
Si ko ese wa LO.

4 cr Fi opin si aigbagbo wa
K‘O si da wa n‘ide;
Jek‘a kedun fun ese wa.
K‘aler‘ alafia.

5 mp Re wa sile, tun gbe wa ro


Si bukun otosi;
Je k‘a mo riri arun wa,
Ati iwosan re.
6 Jek‘ a mo ebi ese wa.
Sim‘ebi na Kuro;
We okan ti ese ndamu
N‘nu eje etutu.

7 F‘ ipo ewu t‘a wa han wa,


Si f‘ese wa ji wa;
Se wa pe ni iwa-mimo,
Si mu wa lo s‘orun.
Amin.

246 L.M
E wa sodo mi gbogbo enyin ti nsise,
emi o si fi isimi fun yin. Mat. 11:28.

1 cr Jesu ‘Wo ore elelse,


Mo wa ‘ranwo wa sodo Re,
Aye ati ese su mi,
Na apa Re k‘O si gba mi!

2 mf Fi anu wo okan mi san;


‘Wo l‘o le se awotan mi;
di Mo ti subu, mo si segbe,
K‘aworan Re to tan n‘nu mi

3 Pese ‘bugbe na fun ‘ra Re,


Fi ife wonu okan mi;
Bayi ni mo le di mimo,
Ti ese ki o ba mi gbe.

4 Mo jewo pe agbara mi
Ko le mu mi ye ni Tire;
cr Jesu, ise na Tire ni,
Mo jewo gbogbo re fun O.

5 mf Kini uno fi ro ore Re?


Ese ni mi, ife ni O;
p Eyi nikan l‘ebe mi pe
pp Mo segbe, sugbon,
‘Wo ti ku!
Amin.

247 7.7.7.7.7.7
Olorun sanu fun mi, emi elese.
Lk. 18:13.

1 mf Olugbala lsrael,
Wo mi lat‘ ori‘te Re;
F‘ ikanu oto fun mi
cr Mu okan lile mi ro;
So okuta di eran;
Wo mi, si fo okan mi!

2 cr Baba, nipa Emi Re


Fi gbogbo ese mi han,
Ki nmo ese ti mo da
S‘ imole at‘ife Re;
Ese t‘o kan Jesu mi,
T‘o ta eje Re sile.

3 di Jesu, wa agutan Re,


Mu mi pada to O wa,
p Jeki nwo 0 ki nsokun
Kikoro bi Peteru,
mf Ki nle wi nip‘or‘ofe,
Iwo mo pe mo fe O!

4 Ki nwa si iwaju Re,


B‘ agbowode ni ti se,
Ki nduro li okere,
Ki nlu okan-aya mi;
p Elese ko l‘ ebe ju
Olorun, sanu fun mi!

5 cr Jo ranti mi fun rere,


L‘afonifoji aye;
F‘eje etutu han mi,
‘Gbat‘ are mu okan mi,
Jeki nfi itara ri
Jesu ti a pa fun mi!
Amin.

248 S.M
Nitori ife Kristi nro wa. IIKor. 5:14.

1 A! nibo ni mba lo,


Pelu ese nla mi
Tani mba f‘ iponju mi han
Ti mba ro ‘jo mi fun?

2 Olugbala npe mi;


Ese ti mo duro?
O npe elese t‘are mu,
Sibe mo fa seyin

3 Ki l‘o fa mi seyin
Ti nko le fi sile
Ti ki o jek‘ Olugbala
Gba gbogbo okan mi.
4 Ohun egun aimo
T‘o sa lumo ninu
Orisa ti nko fe jewo
Ese ‘koko n‘nu mi.

5 Jesu, fi‘dena na
Ti nko fe ri, han mi;
Jeki nle wadi ohun na
Ti nle mi l‘odo Re.

6 Oluwa di okan
F‘ ipa Re han n‘nu mi;
Tan ‘mole si okunkun mi,
'K‘o si ‘boju kuro.

7 Mo gbagbe wayi pe .
Anu mbe ninu Re;
Oluwa, jek‘ o ri fun mi
Gege b‘igbagbo mi!

8 Iwo nfe mu‘dena


Ti njbe n‘nu mi kuro;
Mu kuro, un o si jewo pe
Kiki ‘fe l‘Olorun
Amin.

249 8.8.8.D.
Oluwa, sanu fun mi, nitori ailera mi.
OD. 6:2.

1 cr Olorun mi, Olorun mi!


O to ge, nki o sako mo;
Nko ra eje Re mole mo,
Nko tun tan O ni suru mo;
di Nko fa ‘binu Re f‘ese mo,
p Nko dese si ife Re mo.

2 mf Jesu, b‘anu mbe lodo Re,


Da gbogbo re le mi lori;
cr Emi olori elese,
T‘o nm‘ imi-edun f‘anu Re,
Mu mi bo s‘ or‘-ofe Baba,
Ma jeki mbi O ninu mo.

3 Orisun ife ti ki gbe,


Jesu Abanikedun, gbo;
Olugbala mi li oke,
cr S‘Alagbawi mi l‘ekan si,
F‘ igbagbo on ‘fiji fun mi;
mp Jo jeki nyipada, ki nye!
Amin.

250 L.M
Emi o fe O, Oluwa agbara mi
OD. 18:1.

1 mf Olorun, kil 'emi y'o mi


Wa fi wole niwaju Re?
Kini uno ti ri l‘oju Re?
Kini un o mu wa gb‘ or‘-ofe?

2 cr Eni nfe oju rere Re


Ko le se lair in lona Re;
K‘o fe oto ati anu,
K‘o f‘igbagbo b‘Olprun rin.

3 Mba je Tire lat‘oni lo,


Ese mi atijo si mbe;
Bi mo f ohun gbogbo fun O
Tire ni mo fun O pada.

4 mf Nje, kini mo le gbekele?


Nko l‘ohun kan, asan ni mi,
Gbogbo fuja mi la sati
Itiju gbe ogo mi mi.

5 cr Mo j‘elebi niwaju Re,


Lori mi n‘ binu Re mbe;
p O to k‘a je mi ni iya;
Oto; sugbon Jesu ti ku!

6 cr Jesu ti ta ‘je Re sile,


O ru ese wa lor‘ igi;
mp O teriba lab‘ egun wa;
p O pari! O ti ku fun mi.

7 cr Wo t‘o duro niwaju‘te


O ngbadura ti y‘o bori
O nf‘iha, at‘owo Re han,
Pe, a ko ‘ruko mi sibe

8 O mbe laelae lati bebe;


Pe ki nle joba pelu Re
F Amin s‘eyi t‘Oluwa wi!
ff Jesu ki O bebe lasan
Amin

251 8.8.8.D.
Tali Olorun bi IWO ti o ndari
Aise dede ji. Mika 7:18.
1 mf Olorun ‗yanu ogo Re,
Nhan ninu gbogbo ise Re,
Sugbon or‘ofe ‘dariji,
Je ohun iyanu julo
Olorun tani dabi Re,
Ore tani po bi Tire?

2 mp N‘iyanu at‘ayo l‘a gba


Idariji Olorun wa,
‘Dariji f‘ese to tobi
T‘eje Jesu s‘etutu fun,
Olorun tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?

3 cr ‘Dariji lat‘ow‘ Olorun


‘Dariji fese to tobi
‘Dariji ni p‘eje Jesu
‘Dariji m‘olote wa ‘le
Olorun, tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?

4 p Jo, je k‘ore-ofe Re yi
Ife iyanu nla Re yi
cr Fi iyin kun gbogbo aye,
Bi t‘egbe akorin l‘oke
Olorun, tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?
Amin.

252 L.M & Ref


Ibukun ni fun awon ti a dari
Aisedede Won ji, ti a si bo ese
won mole. OD. 32:1.

1 mf E ro didun nit‘ese mi.


T‘a sin s‘abe omi okun
‘Gbati agbara Olorun
Dide fun ‘gbala okan mi.
F ―Iwo yooo ran ese won lo s‘ogbo okun‖
Ileri Oluwa ni, o si to fun mi
B‘omi okun tile nho pelu bibi re
Y‘o rele, y‘o si gbe, ko le de odo mi
Nitori Olorun nikan l‘o kawo igbi-
Omi nla ti ‘nu okun.

2 mf Won ki y‘o tun gb‘ogun ti mi,


Tabi yo okan mi lenu,
cr ‘Tori agbara Olorun
Ni y‘o mu idariji wa.

3 mf Ko si wahala to le mu
Ese mi wa si iranti,
F Okan mi s‘owon l‘oju Re,
Y‘o d‘abobo nigbagbogbo.
Amin.

253 7.6.7.7. & Ref.


Bi iwo ba rewesi li OJO iponju,
agbara re ko to nkan. Owe 24:10.

1 mf M o gbo Jesu wipe


―Agbara re kere‖
Alare, sora, gbadua,
Pipe re mbe lodo mi.
F Jesu san gbogbo
‘Gbese ti mo je,
Ese to m‘abawon wa
Lo ti fo nu kuro.

2 cr Oluwa, toto mo mo
P‘ agbara Re nikan
Le s‘adete di mimo,
O le m‘okan lile ro.

3 Ko si ‘re ‘kan ti mo ni
Lati ni ore Re,
Em‘o fo aso mi mo
N‘n‘ eje Jesu Oluwa.

4 p Gbati ‘pe ‘keyin ba dun


T‘o n pe mi s‘odo Re,
Jesu ti san gbogbo re,
E m‘o ba g‘oke orun.

5 cr N‘iwaju ‘te uno duro


N‘nu pipe ewa Kristi
Un o fi ade ogo ni
Lel li ese Jesu.
Amin.

254 CM.
Isun kan yio ,si sile fun ese
ati iwa aimo. Sek. 13:1.

1 mf Isun kan wu to kun f‘eje


T‘ o ti ‘ha Jesu yo,
Elese mokun ninu re,
O bo ninu ebi.
2 mp ‘Gbamo figbagbo r‘isun na,
Ti nsan fun eje Re,
Irapada d‘orin fun mi
Ti uno ma ko titi.

3 f Orin t‘odun ju eyi lo


Li emi o ma ko;
‘Gbati ore-ofe Re ba
Mu mi de odo Re-

4 mf Mo gbagbo p‘O pese fun mi


Bi mo tile s‘aiye,
Ebun ofe t‘a feje ra
Ati duru wura.

5 Duru t‘a t‘ow‘ Olorun se,


Ti ko ni baje lae,
Ti ao ma fi yin Baba wa
Oruko Re nikan.
Amin.

255 7.6.7.6.D.&Ref.
Eyi ha ise akoko ati gba fadaka
ati lati gba ASO; II A. Oba 5:26.

1 mf Ako fi oro ra mi,


Fadaka on wura,
Uno jijakadi f‘orun,
Uno si wo ‘nu agbo;
N‘nu iwe Ijoba Re
Ti o Fewa pupo,
So fun mi Oluwa mi,
Oko mi ha wa nbe?
cr Oko mi ha wa nbe?
Ninu iwe nla ni
Iwe ti Ijoba Re
Oko mi ha wa nbe?

2 cr Oluwa, ese mi po,


Bi iyanrin okun.
Sugbon eje Re, Jesu
Ti to fun gbogbo re.
‘Tori ‘WO ti se‘leri
Ninu oro Re pe;
‖B‘ese re pon b‘ododo,
Un o fo won fun bi owu.‖

3 f N‘ilu daradara ni
At‘ opo ‘bugbe Re,
Nibit‘ awon mimo wa
Nin‘aso funfun won,
T‘ohun eri ko le de
Lati b‘ewa re je,
‘Bi t‘awon angeli nso,
Oko mi ha wa nbe?
Amin.

256 L.M.
Bere ohun ti Emi o fi fun o. IA. Qba 3:5.

1 mf Oluwa, Iwo ha wipe


Ki mbere ohun ti mo fe
Jo, je ki mbo Iowo ebi,
Ati low‘ese on esu.

Cr Jo, fi ara Re han fun mi,


Si je ki nru aworan Re,
Te ite Re si okan mi,
Si ma nikan joba nibe.

Mf Jeki nmo p‘O dariji mi,


Ki ayo Re s' agbara mi,
F Ki nmo giga, ibu, jinjin
Ati gigun ife nla Re.

Cr Eyi nikan ni ebe mi


Eyi t‘o ku di owo Re
Iye, iku, aini, oro
Ko je nkan b‘O ba je t‘emi.
Amin

257 C.M.
A won ti o ti gba opolopo ore
Ore Ofe ati ebun ododo yio
joba ninu iye.
Rom. 5:17.

1 f Ore-ofe! b‘o ti dun to!


T‘o gba em‘ abosi;
cr Mo ti sonu, O wa mi ri,
O si si mi loju.

2 cr Or‘ofe ko mi ki m‘beru,
O si l‘eru mi LO
B‘ore-ofe na ti han to
Nigba mo ko gbagbo!

3 mf Opo ewu at‘ idekun


Ni mo ti la koja;
F Or‘-ofe npa mi mo doni
Y‘o si sin mi dele.

4 f Leyin aimoye odun n‘be


T‘a si nran bi orun,
Gbogb‘ ojo tao fi ‘yin Re
Y‘o ju ‘gba ‘saju lo.
Amin.

258 7.7.7.7.D.
Oluwa odo Re ni mo sa pamo si.
OD. 143:9.

1 mp Jesu Oluf‘okan mi,


Je ki nsala s‘aya Re,
cr Sa t‘irumi sunmo mi.
Sa ti iji nfe soke;
mf Pa mi mo, Olugbala
Tit‘ iji aye y‘o pin,
di To mi lo s‘ebute Re,
p Nikeyin, gba Okan mi.

2 mf Abo mi, emi ko ni,


IWO l‘okan mi ro mo;
di Ma femi nikan sile;
Gba, mi si tu mi ninu,
cr IWO ni mo gbekele;
IWO n‘iranlowo mi;
mf Ma sai fiye apa Re
Dabo b‘ori aibo mi.

3 mf Krist‘ ‘Wo nikan ni mo fe;


N‘nu Re mo r‘ohun gbogbo
Gb‘eni to subu dide,
W‘alaisan, to afoju,
Ododo l‘oruko Re,
p Alais‘ododo l‘emi
Mo kun fun ese pupo,
mf Iwo kun fun ododo.

4 cr ‘WO l‘opo ore-ofe,


Lati fi bo ese mi;
Je ki omi iwosan
We inu Okan mi mo;
F IWO l‘orisun iye,
Je ki mbu n‘nu Re l‘ofe,
Ru jade n‘nu okan mi,
Si iye ainipekun.
Amin.
259 9.8.9.8.& Ref.
E mayo ninu Oluwa nigba gbogbo,
mo si tun wi, ―E mayo. ‖ Fili. 4:4.

1 O mi nyo ninu Oluwa


‘Tori O je iye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo
Adun ni lati r‘oju Re.
Emi nyo-ninu Re
Emi nyo ninu Re
Gba gbogbo lo fayo kun okan mi
‘Tori emi nyo n‘nu Re.

2 O ti pe t‘O ti nwa mi kiri,


‘Gbati mo rin jina s‘agbo,
O gbe mi wa sile l‘apa Re
Nibiti papa tutu wa.

3 Ire at‘anu Re yi mi ka,


Or‘-ofe Re nsan bi odo,
Emi Re nto, o si nse ‘tunu,
O mba mi LO si ‘bikibi.

4 Emi y‘o dabi Re ni ‘jo kan,


Uno s‘eru wu womi kale,
Titi di ‘gbana uno s‘oloto,
Ni sise os0 f‘ade Re.
Amin.

260 6.6.6.6.8.8.
Awa ni alagbawi kan lodo Baba,
Jesu Kristi Olododo. I Jn. 2:1.

1 f Dide, emi mi, nde


Gbon eru ebi re,
Eni t‘a pa fun mi,
F‘arahan n‘tori mi:
Mo l‘Onigbowo n‘idi ‘te,
A ko ‘ruko mi S‘OWO Re.

2 f O mbe l‘oke laelae


Lati bebe fun mi,
On nf ife ‘rapada
At‘eje Re bebe,
di Eje Re se ‘tu gbogb' aye
O mbu won ile or‘-ofe

3 p Ogbe marun l'o gba


Li oke Kalfari;
cr Won ngbadura aitase,
Won mbebe n‘tori mi,
p Won nke, ―Dariji, dariji''
Ma je k‘elese na ko ku!

4 mp Baba gb‘ebe eni


Ami ororo Re,
Ko le ko adura
Ti omo Re owon,
Emi Re ndahun ebe na
Pe, ―Mo d‘atunbi, Olorun‖

5 mf Mo b‘Olorun laja,
cr Mo gb‘ohun Tiji Re,
O SO mi d‘omo Re,
Emi ko beru mo;
F Mo fi ‘gboya sunmo ‘do Re,
Mo si nke pe, ―Abba Baba.‖
Amin.

261 S.M. & Ref.


Ore ofe Jesu Kristi Oluwa ki o
pelu nyin. IKor. 16:23.

1 f Ore-ofe, l‘ oko
Adun ni l‘eti wa;
Gbohun-gbohun re y‘o gba
orun kan
Aye y‘o gbo pelu.
ff Ore-Ofe sa
N‘igbekele mi,
p Jesu ku fun araye,
pp O ku fun mi pelu.

2 f Ore-ofe l‘o ko
Oruko mi l‘orun
L‘o fi mi fun Od‘agutan,
T‘O gba iya mi je-

3 mp Ore-Ofe to mi
S‘ona alafia,
O ntoju mi l‘ojojumo
Ni irin ajo mi.

4 mf Ore-ofe ko mi
Bi a ti ‘gbadura;
Cr O pa mi mo titi d‘oni,
Kosi je ki nsako.

5 f Je k‘ ore-ofe yi
F‘agbara fokan mi;
mf Ki nle fi gbogbo ipa mi
At‘ ojo mi fun O
Amin.

262 D.L.M.
Ki ise nipa ise ti awa se ninu ododo,
sugbon gegebi anu Re li o gba wa la. Titu 3:5.

1 mf Ajigbese opo anu,


Un o korin iyin anu Re,
F ASO ododo Olorun
Ni mo gbe wO; eru ko si;
Ofin ko le da mi l‘ebi,
Ore-Ofe so mi d‘ominira,
Igboran Olugbala mi,
At‘ eje Re, bo ese mi.

2 f Ise rere t‘oti bere,


Apa Re y‘o se l‘asepe;
Gbogbo ileri rere Re,
Beni, Amin! ni titi lae;
mf Tani le ya wa ninu Krist‘?
Ohun ti mbo, t‘isisiyi?
Ko si l‘aye, ko si l‘orun
T‘o le mu ipinu Re ye

3 f Oruko mi mbe LOWO Re


Nko r‘eni ti o le pare,
Ami or‘ ofe lara mi,
Mo wa li okan aya Re;
Uno foriti titi d‘opin,
Mo d‘ohun ini Olorun,
Ayo orun mbe l‘okan mi,
Pel‘ awon t‘a ti se Togo.
Amin.

263 9.1.9.1. & Ref.


Enyin si nyo ayo ti a ko lefi
enu SO ti o si kunfun ogo. I Pet. 1:8.

1 cr M o ti de ile ore-ofe
O to fun gbogb‘ aini mi
Nigbati mo joko l‘ese Re.
O si so mi d‘ominira.
F Ayo nla ni, ayo ti Jesu nfifun
ni,
Ayo ti enu ko le so,
Ayo nla ni, ayo ti o kun fun
ogo,
Ayo ti a ko le royin tan.
2 f ‗Mo ti de ile igbadun nla,
Alafia mbe ninu mi;
Ibukun ti o kun wosile,
Mp Mo bo l‘owo ese mi.

3 cr Mo ti ni ireti t‘o daju,


Ninu ore-ofe Re
Olugbala mi mbe pelu mi,
O nrerin si omo Re

4 f Mo l‘ayo ti enu ko le so,


Ogo ayo na npo si
Bi kanga om‘iye ninu mi ‘
Jojumo l‘o nru soke.
Amin.

264 C.M.
Olori Alufa to ba ni kedun ni
inu ailera wa. Heb. 4:15.

1 cr Afayo ro ore-ofe
T‘ Alufa giga wa;
Okan Re kun fun iyonu;
Inu Renyo fun ‘fe.

2 mp Tinu-tinu l‘On daro wa,


O mo ailera wa:
O mo bi idanwo ti ri, Nitori O ti ri.

3 cr On papa lojo aye Re


p O sokun kikoro;
O mba olukuluku pin
Ninu iya ti nje.

4 mf Jek‘ a figbagbo, irele


W‘anu at‘ipa Re;
Awa o si ri igbala
L‘akoko iyonu.
Amin.

265 L.M.
Ibukun nifun Okunrin na
ti o wa ogbon ri. Owe 3:13.

1 f Alabukun l‘eni t‘ori


Ore-ofe Olorun gba,
Ogbon t‘o t‘oke sokale,
Igbagbo t‘o nfi ‗fe sise.
2 f Ibukun t‘a ko le juwe
Ni t‘eni mo ‘yi ‘ku Jesu,
Ebun t‘a ko le fenu so,
Oye orun y‘o je tire

3 mf Ogbon orun; tani le so


lye owo t‘a le fi ra?
Ogbon fuyi pupopupo
Ju fadaka on wura lo.

4 Emi gigun mbe lowo re,


Oro at‘iyin ti kiku,
Oro Kristi t‘a fi Ji wa,
Pel‘ ola t‘Olorun nfun wa

5 f Ayo pipe l‘Ope wasi


Pelu adun mimo gbogbo;
Ona didara l‘ona Re,
Gbogbo ‘pa Re kun f‘alafia.

6 ‘Bukun nit‘eni ri ogbon.


T‘o si di mu titi d‘opin!
Ini rere ni tire lae;
Kristi, Ogbon, at‘orun j‘okan.
Amin.

266 7.7.7.7.7.7

Pa oju Re mo kuro lara ese mi ki


iwo ki o si nu gbogbo aisedede mi nu kuro. OD. 51:9.

1 mf Jesu, f‘oju anu Re,


Mu k‘ibanuje mi tan;
Nibo lelese ba lo?
Iwo l‘Ore elese,
Mo fe wa ‘simi n‘nu Re
Emi otos‘elese

2 mp Yara, jo yara gba mi!


Yo mi kuro n‘nu ‘leru,
Gba mi lowo ese mi!
N‘itor‘ ife at‘ anu Re;
S‘okan mi di ominira
F‘agbara Re han n‘nu mi.

3 cr Emi otosi julo,


Alaimo at‘ eleri;
Emi t‘o jinna si O,
T‘o kun fosi at‘ese;
Fi apa ife gba mi,
Ki O si dariji mi!

4 cr Jesu, l‘oko Re nikan


Ni mo n‘ireti ‘gbala,
Mo wa l‘owo anu Re
Gba mi, gba mi la d‘opin
F‘opo or‘-Qfe fun mi,
Gba mi la s‘orun mimo.
Amin.

267 7.6.7.6.7.6.D.
A won oke nla ati awon oke
Kekeke yio bu si orin niwaju yin.
Isa. 55:12.

1 f Gbogb‘ aye kun fun orin,


Mo ngbo nibi gbogbo;
Awon ‘tanna papa ndun
Layo n‘nu afefe.
Loke, li ayika mi,
Orin jeje nyin lo
Oba ogo wa mi ri,
Orin wa n‘n‘ okan mi!
mf Eje Jesu Kristi nsan,
Igbi Re yi mi ka;
Ife mole lokan mi,
Orin wa n‘n‘okan mi!

2 cr Teleri, imi edun


Li okan mi ma nfe;
Nitori ailera mi
Ni o se fi ri be
Nigba mo fokan mi fun
Oro Re wo mi san,
Lae mo wa lodo Kristi
Orin wa ri‘n‘okan mi!

3 mp Gbogb‘ aye mi ti kun fun,


‘Banuje at‘aro;
Sugbon lat‘isiyi lo
Ororo ayo de;
Adura d‘orin iyin
Mo si wa nlepa nso
Ni adura at‘ise
Orin wa n‘n‘okan mi!

4 f Beni okan mi si nyo


Si oro Oluwa;
Gbogbo ‘gba lo si nkorin
Gege b‘awon eye;
Emi ko mo ibiti
Orin harp na ti ndun,
mp Mo mo p‘orun sunmo mi.
F Orin wan‘n‘ okan mi.
Amin.

268 7.6.8.6.7.6.7.6.
Ore-ofe a ti fi gba yin la nipa
igbagbo Efe. 2:8.

1 mp Ore ofe nipa ‘gbagbo


Lo so mi d‘atunbi
Kise nipa ‘se owo mi
mf Sugbon ti Kristi t‘a pa;
N‘nu Re mo d‘eda titun,
‘Reti miran, asan;
Or‘ ofe nipa ‘gbagbo
Loso mi d‘atunbi.

2 mp Or‘ ofe nipa ‘gbagbo


Lo gba mi low‘ese;
F Eru ebi na ti folo;
Alafia wa njoba;
Sodo Krist‘ Olugbala
Uno koa sakolo;
Or‘ ofe nipa ‘gbagbo
Nikan lo gba mi la.

3 f Or‘ ofe nipa ‘gbagbo,


Ayo ‘yanu n‘temi!
Ebun ife orun fun mi
N‘iye ainipekun;
Bi mo tile s‘alaiye;
Ife Re ni mole mi;
Or‘ ofe nipa ‘gbagbo;
Ayo ‘yanu n‘ temi.
Amin.

269 10.8.10.8. & Ref


Isun kan yio si silefun
ese ati fun iwa aimo. Sek. 13:1.

1 mp Mo ti de ‘bi orisun ‘wenumo,


Mo ri sinu eje ti nsan
Jade lat‘ ori oke Kalfari
T‘o m‘okan mi di mimo lau.
F Daju okan mi di mimo;
Mo mo p‘eje Kristi we mo
O si ngbe inu mi,
O mu k‘okan mi di mimo
2 mp Mo ti de ‘bi orisun ‘wenu mo
Alafia pipe je temi;
Nipa or‘-ofe
O fese mi ji,
Alafia de ‘nu okan mi.

3 f Mo ti de ‘bi orisun ‘wenumo,


Ogo si kun ‘nu okan mi;
ff Aleluya! mo ni ayo kikun,
‘Tori mo di mimo laulau.
Amin

270 10.10.10.10 & Ref.


Nigbati okan ninu WON ripe a
mu on larada o pada, o si yin
Olorun l‘ogo. Lk. 17:15.

1 mf Etutu eje Krist‘ t‘a ta sile,


mp Lori ‘gi Kalfari l‘o gba mi la,
Sugbon mo nfe isun to ju yi lo
Ekun ibukun Re l‘okan mi nfe
lati mo.
F Mo ngbe l‘aye bi l‘orun,
Mo f‘aye mi fun Jesu,
Mo l‘ayo ninu ominira ti O
fun mi;
Oro na ti On ti SO
Tija gbogbo ide mi;
‘Seju kokan aye mi si je
‘bukun orun.

2 f T‘emi l‘ayo lat‘orisun ife


Ebun Orun yi lo wu mi julo.
Mo si wa ni alafia pipe
Nigbati emi Re fun mi l‘oro ominira.

3 mf Iwo fe mo ekun ore Baba?


IWO fe gbe n‘nu ibu oro Re?
F Gbagbo; ileri Re otito ni;
Si gba ominira t‘o ni ‘bukun t‘O fi fun O
Amin.

271 10.9.10.9.D.
Nigbati awa je elese,
Kristi ku fun wa. Rom. 5:8.

1 mf Lekan mo wa ninu ide ese


Bi eru nko si le ja ‘jabo;
F Sugbon mo ri idande ologo,
Gba Jesu ja ide mi sonu.
F Ominira ologo at‘iyanu
Nko si ninu ide ese mo,
Jesu Oludande at‘ologo
Y‘O je t‘emi loni, titi lae

2 mp Omnira kuro n‘nu ife ara,


Owu, ikorira on ija;
Omnira kuro n‘nu asan aye
Ati gbogbo ikoro aye.

3 mf Omnira low‘ ese igberaga,


Ife owo egbin on wura,
Ero ibi at‘ oro ibinu
Omnira ayo at‘ologo.

4 f Omnira lowo ‘beru on ‘rora,


Lowo aniyan at‘edun re,
Omnira n‘nu Krist‘ Olurapada
Enit‘O jaide mi sonu.
Amin.

272 6.6.10.D.&Ref.
Ki a si gbe Olorun
Igbala mi soke. OD. 18:46.

i f Gba Jesu wo mi san


N‘ife Re han si mi;
Gbogb‘ ese mi l‘Olugbala ko lo
Ayo yi po pupo
B‘igbi n‘ nu okan mi,
Beni ‘fe na nposi lojojumo,
F Be n‘ife na npo si lojojumo
Mo fe Ona toro t‘atijo ni;
Ayo kun okan mi
Gba Jesu wo mi san,
Be n‘ife na npo si lojojumo

2 mp Mo fi ese sile,
Aye at‘ ogo re,
Nisiyi, mo wa l‘ona didara,
Mo si ni alafia,
mf Mo bo lowo ‘foya,
Be n‘ife na npo si lojojumo.

3 f Un o sin l‘aye yi,


B‘aye tile nfo lo,
Laipe Oluwa yo de n‘nu ogo;
ff Eyi mo mo daju,
Ti nmu inu mi dun;
Ife Re npo si ninu okan mi.
Amin.

273 12.11.12.12. & Ref.


Enikeni ti o ba to mi wa,
Emi ki yio taa nu bi o ti wu ki o ri. Jn. 6:3 7.

1 mf ‘Gba mo t‘Oba mi wa pelu okan tite,


Ti mo mbebe for‘ofe n‘iwaju ‘te Re,
F Ayo ti mo ri l‘oju Re bo ti dun to!
B‘ayaba Esther, O n‘opa anu si mi.
ff Opa ife loje ati t‘idariji,
L‘ofe si ni opa anu na,
Oba orun b‘oju wo ‘le lat‘oke
O si na opa na si mi.

2 mp Mo ti sako jina to ninu ese mi;


Ninu ope mo ti padanu pupo,
cr Mo so ‘reti nu ‘gbat‘ o ku emi nikan,
Mo gb‘ohun adun Re, sunmo ‘te mimo

3 cr Bi ‘wo ba je le f okan re fun Krist‘ Oba


Y‘o fi se ‘le, ko si ni kuro nibe,
F Sa ronupiwada, ayo y‘o je tire,
Nitori Jesu y‘O n‘opa anu si O
Amin.

274 11.11.11.11. & Ref


Olufe mi ni temi, emi si ni Tirpe. O. Sol 2:16

1 mf Lekan mo nwa ‘bukun, ‘wosan ore Re


Nisiyi, Olorun papa ni mo nfe,
Oluwa funrare t‘is‘Olubukun
Nikan soso ni mo nfe nisisiyi.
ff Jesu! Jesu! Jesu!
L‘em‘o ko titi;
Gbogb‘ ohun ti mo nfe
Ni mo ri ninu Re.

2 cr Lekan mo ngbiyanju laini igbala,


Nisisiyi mo ni igbala pipe;
Laini ‘gbagbo ‘gbi aye ngba mi kiri,
On ti di mi mu, ‘dakoro mi ko ye

3 mp Lekan mo ns‘aniyan, mo nsiyemeji;


Lekan mo nyan le Oluwa mi lowo,
Lekan mo nsi bere ninu adura,
Ife Jesu nikan ni sise loni.

4 mf Lekan, mo n‘ireti n‘nu ‘se owo mi,


Lekan, mo nfe aye ati ogo re,
Lekan, ife ti inu mi ni mo nse,
Loni mo d‘ohun elo fun Oluwa.

5 Mo ti nreti Jesu, loni t‘emi ni;


Lekan, mo ngbe oku igbagbo kiri,
Lekan, emi ko ni ireti iye,
Nisiyi bibo Re je ayo fun mi.
Amin.

275 10.10.9.9.& Ref.


Ore-ofe li a fi gba yin la Efe. 2:8.

1 mf Ninu aini nimo to Jesu wa,


Ore-ofe Re lo da mi l‘ola,
cr Nko je gberaga, nko je hale,
Ore-ofe Re lo gba mila
mp Ore-ofe lo gba mi la,
Ore-ofe lo gba mi la,
F Eyi l‘oro na, Ogo ni f Olorun;
Ore-ofe Re lo gba mi la.

2 mf Lekan ese ti njoba l‘okan mi,


Mo sako jinna lodo Oluwa,
Jesu wa mi ri, mo ti l‘ayo,
Ore-Ofe Re lo gba mi la.

3 mp Ekun ko le mu ‘re kan wa fun mi,


Anu Re nikan lo fi gba mi la,
cr Ese ti mu ki nma beru ri,
Sugbon or‘-ofe ti gba mi la.

4 mf Je ki elese t‘ago re ti kun,


So ife Olugbala re kiri,
Un o ma tun itan naSO titi,
Ore-ofe Re lo gba mi la.
Amin.

276 S.M.
Okari mi nfa nitoto, o tile pe ongbe
fun agbala Oluwa: aya mi ati ara
mi nkigbe si Olorun alaye. OD. 84:2.

1 p ‗Wo Oluwa oke,


Ati abe sanma;
Mo dobale li ese Re,
Mo nke fun anu Re

2 p Dari‘were ji mi.
Ese ti mo ti da;
SO fun okan ofo, po ye
Nip‘ Omo bibi Re

3 p Ebi, bi eru nla


Wa l‘ori Okan mi.
IWO ni mo ro edun fun,
‘Wo ni mo sokun ba.

4 Inira ti mori,
‘WO lo le mu kuro;
Oluwa f‘idariji han,
At‘ opo ife Re.

5 p Oju anu Re kan


Ko f‘aya mi bale
Je ki nmo pe adariji mi,
Un o d‘alabukun fun.
Amin.

277 CM
Bikosepe a tun eniyan bi nipa omi ati nipa
Emi on ki yoo le WO ijoba Olorun. Jn. 3:5.

1 f Eyi l‘ase nla Jehofa


Yoo wa titi lae
Elese b‘iwo at‘ emi,
K‘a tun gbogbo wa bi.

2 pOkunkun y‘o je ipa wa,


B‘ a wa ninu ese;
A ki o ri ijoba Re,
Bi a ko d‘ atunbi.

3 Bi baptisi wa je ‘gbarun,
Asan ni gbogbo re;
Eyi ko le w‘ ese wa nu,
Bi a ko tun wa bi.

4 Wo ise were ti a nse,


Ko ni iranwo Re;
Won ko s‘okan wa di otun,
B‘ awa ko d‘atunbi.

5 F LO kuro ninu ese re


cr Ja ewon Esu nu;
f Gba Kristi gbo tokantokan
ff Iwo o d‘atunbi.
Amin.

278 C.M.
Omokonrin, tujuka, a dari
ese re ji o. Mat. 9:2.

1 p E bi ese npa mi l‘eru,


O te ori mi ba,
Oluwa fi okan eran
Paro t‘okuta mi.

2 Mo de, eru ese npa mi,


Iku mba mi l‘eru;
F‘eje Re te ‘dariji mi,
Si le eru mi lo.

3 Okan mi ke le r‘isimi
Titi uno fi kigbe
p Li abe agbelebu Re,
Pe, ―Jesu ku fun mi,‖

4 Fun mi lati ni igbagbo,


Ati iriri yi,
Titi iwa ogbo yoo lo,
T‘okan mi yoo d‘otun.
Amin.

279 L.M.
A WON omo Israeli si wi fun Oluwa pe,
A wa ti se: ohunkohun ti o ba to
li oju re ni ki ofi wa se;
sa gba wa li oniyi, awa be o. A. Oni. 10:15.

1 p Oluwa, sanu, dariji;


Da okan t‘o yipada si;
Ki se pe anu Re tobi
Ijilese ko le ro mo O?

2 Ese mi po, jugbon ko le


Ju agbara ore Re lo:
Titobi Re ko ni opin,
Be ge ni k‘a ri ife Re

3 p We ese kuro l‘okan mi,


Si mu okan ebi mi mo
Lokan mi ni feru na wa,
Ese ehin ro mi l‘oju.

4 Ese mi f itiju jewo


Ete s‘ofin at‘ore Re:
Bi idajo Re yoo ba le,
Mo j‘ebi, are niTire.
5 p B‘idajo kan Kan gb‘emi mi,
L‘oju ‘kuuno da Ol‘are,
B‘a si ran mi lo s‘iparun
Tito ni l‘oju ofin Re*

6 Sibe, gba elese t‘o ngbon,


Ti ireti re nra baba,
Bi o le r‘ileri didun
Lati ba le n‘nu oro Re
Amin.

280 C.M.
Olorun sanu fun elese Lk. 18:13.

1 mf Oluwa, b‘agbowode ni,


Mo gb‘okan mi le O:
Oluwa, f ore-ofe wi,
p K‘ o se anu fun ml.

2 mf Mo lu aiduro aya mi,


p Ekun at‘ irora;
K‘o gb‘okan mi ‘nu irora,
p K‘o se anu fun mi.

3 N‘itiju mo jew‘ ese mi,


JO fun mi n‘ ireti;
Mo be, ‘tori eje Jesu,
p K‘o se anu fun mi.

4 Olori elese ni mi,


Ese mi papoju;
Nitori iku Jesu wa,
p K‘o se anu fun mi.

5 Mo duro ti agbelebu,
Nko sa fojiji re:
Ti Olorun t‘o po l‘anu,
p O ti sanu fun mi.
Amin.

281 S.M
Wa, eniyan mi. Isa. 26:20

1 f Baba wa orun npe,


Krist‘ npe wa sodo Re;
Ore wa pelu won o dun,
‘Dapo wa y‘o s‘owon.

2 mp Olorun nkanu mi;


O dar‘ ese mi ji,
Olodumare s‘okan mi.
O f‘ogbon to ‘pa mi.

3 p Ebun Re tipo to!


O l‘opo isura,
T‘at‘owo Olugbala pin,
Ti a feje Re ra!.

4 f Jesu Ori ‘ye mi,


Mo fi bukun fun O;
Alagbawi lodo Baba,
Asaju lodo Re.

5 Okan at‘ife mi,


E duro je nihin;
Titi ‘dapo yoo fi kun
L‘oke orun l'ohun.
Amin.

282 S.M.
Emi korira ara mi, mo si ronupiwada
se toto ninu ekuru ati eru. Job 42:6.

1 Alaimo ni emi,
Olorun Oluwa!
Emi ha gbodo sunmo O,
T‘emi t‘eru ese?

2 Eru ese yi npa


Okan buburu mi
Yio ha si ti buru to,
L‘oju Re mimo ni!

3 Emi o ha si ku,
Ni alainireti?
Mo r‘ayo ninu iku Re,
Fun otosi b‘emi.

4 Eje ni ti o ta
T‘ ise or‘ofe Re;
Le w‘elese t‘o buruju.
Le m‘okan lile ro.

5 pp Mo wole l‘ese Re,


JO k‘o dariji mi
Nihin l‘emi owa titi,
‘WO O wipe, ―Dide‖
Amin.

283 8.8.7. & Ref.


Enyin to tijina rere nigba
atijo ri li a mu yin sunmo
tosi nipa eje Kristi. Efe. 2:13.

1 mf Lekan mo jina s‘Oluwa


Mo nfi ‘wa mi bi ninu
Sugbon Jesu ti gba mi
ff A! bi yo ti dun to
Dun to dun to dun to
A! bi yo ti dun to
Ki Jesu ma gbe inu mi.

2 mp Ibinu ati irunu


Ni ewon t‘esu fi de mi
Jesu ti ja ide na.

3 cr Ifekufe kun' okan mi


Ati igberaga gbogbo
Ina Emi ti jo won

4 f Mo bo lwowo irewesi
LOWO ‘ko gbona ko tutu
ff E ba mi yin Oluwa.

5 f Mo nkorin sa lojojumo
Mo njo mo si tun nfo soke
Nipa agbara Emi

6 mf Eje ‘yebiye we mi mo
Omi iye nsan ninu mi,
F Igbala mi di kikun.

7 f Eyin ara at‘ore mi


Tani ko fe igbala yi
Ofe ni lodo Jesu;
Amin.

284 C.M. & Ref.


Isun kan yio si silefun
ati fun iwa aimo Sek. 13:1.

1 mf Isun kan wa to kun feje,


T‘oti‘ha Jesu yo;
mp Elese mokun ninu re,
O bo ninu ebi.
mf A sa l‘ogbe, n‘tori ‘rekoja,
A si pa lara, n‘tori ese wa,
cr Ina alafia wa mbe l‘ara Re
mf Ina Re lo nwo wa san;
mp A sa l‘ogbe n‘tori ‘rekoja,
A sa l‘ogbe n‘tori ‘rekoja,
ff Ina Re lo nwo wa san,
mf Ina Re nwo wa san.

2 p Ole ni lor‘agbelebu,
mf YO lati ri ‘sun na,
mp Bi mo kun fese bi tire,
cr Mo le we n‘n‘ eje na.

3 mf ‘Gba mo figbagbo r‘isun na


cr Ti nsan fun eje Re
f Irapada d‘orin fun mi,
Ti un o ma ko titi.

4 f Agbara to wa n‘n‘eje yi
Yo wa titi laelae,
ff Tit‘awon eni ‘rapada,
Y o bo sinu ogo.
Amin.

285 C.M. & Ref.


0 fi orin titun si mi li enu OD, 40:3.

1 f M o ni orin kan ti mo fe,


'Gbat O ra mi pada:
T‘Olurapada, Oba mi,
Gbat‘ O ra mi pada.
Mf Gbat‘ O ra mi pada
Gbat‘ O ra mi pada
ff Uno s‘ ogo n‘nu oko Re,
Gbat‘ O ra mi pada;
Un o s‘ogo n‘n‘ oko Olugbala.

2 f Mo ni Kristi t‘O to fun mi,


mp Gbat‘ O ra mi pada;
Sise ‘fe Re, ‘yebiye ni,
Gbat‘ O ra mi pada.

3 mf Mo ni eri nin‘ okan mi,


Gbat‘ O ra mi pada;
Ole ‘yemeji, eru lo,
Gbat‘ O ra ‘mi pada.

4 ff Mo ni ayo ti nko le so,


Gbat‘ O rami pada:
mf Nipa eje ton we mimo,
Gbat‘ O ra mi pada.

5 mf O pese ‘bugbe kan fun mi,


Gbat‘ O ra mi p'ada.
Nibi uno gbe tit‘aye,
Gbat‘O ra mi pada.
Amin.

286 7.7.6.6s
Wo o! emi duro ti ilekun emi si
nkankun Ifi. 3:20.

1 mp A! Jesu, iwo nduro.


Lode, leyin ‘lekun,
lwo fi suru duro
Lati koja sile:
cr ‘Tiju ni fun wa, Kristian,
Awa ti nj‘oko Re!
Itiju gidigidi,
p B‘aba jo Re sode.

2 mf A! Jesu, lwo nkankun,


Owo na si l‘apa;
Egun yi ori Re ka,
Ekun b‘oju Reje:
cr A! ife ‘yanu l‘eyi,
T‘o nfi suru duro!
di A! ese ti ko l‘egbe,
T‘o ha lekun pinpin!

3 p A! Jesu, Iwo mbebe


L‘ohun pelepele,
pp ―Mo ku f‘eyin omo mi
Bayi l‘e se mi si?‖
mf Oluwa, a silekun
N‘ikanu on ‘tiju!
Olugbala, wa wole
Ma fi wa sile lo
Amin.

287 L.M.
Ati ninu olanla Re ma gesin lo .
OD. 45:4.

1 f M ag‘esin lo l‘olanla Re,


Gbo! gbogb‘ aye nke,
―Hosana‖
mp Olugbala, Ma lo pele
Lori im‘ope at‘aso.

2 f Mag‘esin lo l‘olanla Re,


p Ma f irele g‘esin lo ku;
cr Kristi, ‘segun Re bere na
f Lori ese ati iku.
3 f Mag‘esin lo l‘olanla Re,
di Ogun angeli lat‘ orun
p Nfiyanu pelu ikanu
Wo ebo to sun mole yi.

4 f Ma g‘esin lo l‘olanla Re,


mf Ija ikehin na de tan,
f Baba lor‘ite Re lorun
Nreti ayanfe Omo Re.

5 f Mag‘esin LO l‘olanla Re,


p Ma firele g‘esin lo ku,
pp F‘ara da irora feda,
f Leyin na nde, k‘O ma joba.
Amin.

288 7.6.7.6.D.
Hosanna fun Omo Dafidi Mat. 21:9.

ff Gbogb‘ogo, iyin, ola


Fun O Oludande,
S‘Eni t‘awon omode
Nko Hosanna didun!

1 mf ‘Wo l‘Oba Israeli,


Om‘alade Dafid‘
T‘O wa l‘oko Oluwa;
Oba Olubukun,

2 ff Egbe awon Maleka


Nyin O l‘oke giga;
Awa at‘eda gbogbo
Si dapo gbe ‖rin na.

3 f Awon Hebru lo s‘aju


Pelu imo 0pe;
Iyin, adua at - orin
L‘a mu wa ‗waju Re
4 mf Si O s‘aju iya Re,
Won korin iyin won!
‘Wo t‘agbega nisiyi
L‘an korin iyin si.

5 cr ‘WO gba orin iyin won,


Gb‘adura t‘a mu wa,
‘WO ti nyo s‘ohun rere,
Oba wa Olore,
Amin.
289 7.7.7.7.& Ref.
Lati enu awon omo owo ati omo
omu ni Iwo ti mu iyin pe Mat. 21:16.

1 mf Awon ewe Salemu,


f Korin yin oko Jesu,
Awa ewe t‘isiyi,
Jumo yin Olugbala
F Gbo, b‘awon ewe ti nko
Hosana si Oba wa.

2 mf A ko wa k‘a f‘Oluwa,
K‘asi ma ka oro Re,
cr A f ona orun han wa!
F Ogo ni fun Olorun!

3 f K‘oluko, t‘agba t‘ewe,


Jumo gbe orin na ga,
ff Loke-loke, k‘o ma ho
Ki Hosana de orun.
Amin.

290 8.8.8.D.
Yo gidigidi, iwo omobinrin Sioni,
ho, iwo omobinrin Jerusalem,
kiyesi i, oba re mbo wa sodo re. Sek. 9:9.

1 f Iyin, ope at‘olanla


Fun Jesu Kristi Oluwa;
Awon ‘mode nke Hosana
‘Gba Jesu gun ketekete,
Hosana l‘orin wa loni,
Jesu, jowo gba iyin wa.

2 mf A te aso at‘imo ‗pe


S‘ona fun Oba Israel;
O WO Salemu ni ‘rele,
W‘ Oba lori ketekete,
‘WO to we Tempili ni mo,
Gba iyin ati ope wa.

3 ff Hosana s‘Omo Dafidi,


Hosana, e korin didun
S‘Oba to mu ipo ‘rele,
T‘O wa s‘aye l‘awo eda
Fun ise ‘gbala iran wa;
Jesu, jowo gba iyin wa.

4 mp A ba le ri bi On tiri,
A ba le wa bi On ti wa,
K‘agberaga re ‘ra sile
mf Ki ise Jesu lori wa
Le SO wa di omo ‘mole
Ki iyin Re le ma posi.

5 f Jesu Mimo, IWO l‘a yin,


We wa mo bi Tempili Re,
We egbin okan wa kuro,
Je k‘a mo riri ise Re
Ki lala Re ma ba j‘asan;
Si mu wa de ibi iye.
Amin.

291 C.M.
Hosanna fun Omo Dafidi Mat.21:9.

I f ―H osana s‘Omo Dafidi:‖


ff Hosana! e korin!
―Olubukun l‘ eni ti mbo
Loruko Oluwa.‖

2 f ―Hosana s‘Omo Dafidi‖:


L‘egbe Angeli nke;
ff Gbogb‘eda, e jumo gberin,
Hosana! s‘Oba wa.

3 Hosana! awon Heberu


Ja im‘ope s‘ona;
Hosana! a mu ebun wa
Fi tun ona Re se

4 ff T‘agba t‘ewe nke, Hosana!


P Kijiya Re to de;
L‘oni, a si nko Hosana!
B‘o ti njoba loke.
B‘o ti gba 'yin won nigbana,
P Jo, gba ebe wa yi
Lorun, k‘a le b' Angel‘ korin,
ff Hosana s‘Oba wa
Amin.

292 9.8.9.8. A Ref.


Nitori irapada okan
WON iyebiye ni. OD. 49:8.

1 f Irapada! itan iyanu,


Ihin ayo fun gbogbo wa,
Jesu ti ra ‘dariji fun wa,
O san ‘gbese na lor‘igi.
ff A! elese gba ihin na gbo,
Jo gba ihin oto na gbo,
Gbeke re le Olugbala re
T‘O mu igbala fun o wa.

2 mp Omu wa t‘inu‘ku bo si‘ye,


O si SO wa d‘om‘Olorun;
cr Orisun kan si fun elese
We nin‘eje na ko si mo

3 f Ese ki y‘o le joba wa mo


B‘o ti wu ko dan wa wo to,
Nitori Kristi fi ‘rapada
Pa ‘gbara ese run fun wa.

4 f Gba anu t‘Olorun fi lo o.


Sa wa s‘odo Jesu loni
‘Tori y‘o gb‘eni t‘o ba t‘o wa
Ki yi o si da pada lae
Annin.

293 11.8.11.9. & Ref.


Won o ma wo Eni ti agun li OKO Jn. 19:37.

1 mf ‘Gba 'ba fe ya mi kuro lod‘Oluwa,


Mo ranti ‘gi Kalfari ni;
cr Nibi Jesu jiya fun ‘rapada mi
At‘okan t‘a gun l‘oko fun mi.
p Fun mi elese. b‘emi, b‘emi
A gun U l‘oko fun mi;
Mo fi ‘gbagbo ri ni Kalfari:
Okan t‘a gun l‘oko fun mi.

2 mp Ore je eleke On je Oloto,


mf Ife Re pe, ofe si ni
p Mo sokun ‘gba mo ri ‘ra mi nin‘ ese,
cr At‘okan t‘a gun l‘oko fun mi.

3 mf Etutu mimo l‘O ti f‘eje Re se,


Uno ma so itan na titi;
Itan ti Jesu Olurapada mi
At‘okan t‘a gun l‘oko fun mi.
Amin.

294 9.6.10.7.& Ref.


WON kigbe wipe, kan a mo agbelebu,
kan a mo agbelebu. Jn. 19:6.

1 mp O ti ka itan agbelebu,
Nibiti Jesu ku;
Nibiti eje Re iyebiye
Ti san gbogbo gbese re?
pp O ku iku ‘banuje fun o,
O ku iku ‘banuje;
mf A! ife iyanu fun o,
cr O ku iku ‘banuje.

2 mf O ti ka b‘a ti fade egun


De ori Re fun o;
mp ‘Gbat‘O gbadura pe,
―Dariji won Won
Won se alaimokan sa ni.‖

3 mf O ti ka b‘O ti gb‘ole ni la
T‘o n ku lo lor‘igi;
cr Nigbati o fi ikanu wipe,
mp ―Oluwa, jo ranti mi.‖

4 mf O ti ka b‘Otigb‘ojusoke
F TO wipe, ―O pari‖
ff O ti so pe, ―Mo dupe Oluwa,
cr Nitori Oku fun mi‖.
Amin.

295 8.8.8.D.
Eniti On tikara Re fi ara Re
Ru ese wa lori igi. I Pet. 2:24.

1 f Olorun Olufe, kinla!


Eni aiku ti ‘ku fun mi
mf Omo ayeraye Baba
Ru gbogb‘ese mi lor' igi;
cr Eni aiku ti ku fun mi;
Oluwa mi, l‘a kan mo ‘gi.

2 mf Eyin ti nkoja lo, e wo


p B‘eje ti nsan Sara Jesu!
cr £lese wo, Eleda ku,
‘Banuje kan ri bayi ri?
mf Wa, k‘a j‘a nfani eje Re;
Oluwa mi l‘a kan mo ‘gi.

3 mf A kan mo 'gi fun gbogbo wa


K‘a le pada t‘Olorun lo;
E gba oto eri na gbo,
Pe, eje Jesu ti ra yin,
Lodo Re l‘a le ri ‘fiji;
Oluwa mi l‘a kan mo‘gi.

4 f Je k‘a joko t‘agbelebu,


Mf Labe isun iwosan na,
K'a ka ohun gbogbo s'ofo
K‘a fi gbogbo okan wa fun,
cr K‘a ma ro eyi nikan pe,
Oluwa mi l‘a kan mo ‘gi.
Amin.

296 7.7.7.D.
Kinla, enyin ko le ba mi sona
ni wakati kan ? Mat. 26:40.

1 p LOs‘ogba Getsemane,
Gbogbo eyin t‘a ndan wo;
Wo iwaya ‘ ja Jesu;
Ba sona wakati kan!
Ma keyin s‘irora Re
Ko bi Krist‘ ti ngbadura.

2 p Ba lo, si gbongan ‗dajo;


Wo b'Oluwa ti duro;
Ni ‘kedun ati ‗rora,
di A! Ibanuje Re po!
Fi ara da Idanwo.
Ko lati gb'agbelebu.

3 p Gorioke Kalfari
K‘o si wole l‘ese Re.
Kiyesi ‘se ‘yanu na;
di Olorun s‘etu pari
―O pari‖ gbo igbe na;
pp Jeki Krist‘ koo b‘atiku

4 mf Yara lo si iboji
Nibit‘ a gbe te E si;
p Wobi‘ be ti paroro,
Tani gb‘Olugbala lo?
cr Krist‘ ti jinde, a ti ri I:
f Jesu je k‘a jinde be
Amin.

297 L.M
Nigbana ni Jesu ba Won wa si ibikan
ti a npe ni Getsemane. Mat. 26:36.

1 mp Oganjo gan l‘oke Olif,


Awon irawo si ti wo:
Oganjo gan nisisiyi
p Krist‘ nikan ngbadura l‘ogba.

2 mp Oganjo gan lair‘enikan,


Jesu nikan ba eru ja;
Omo-eyin t‘O fe papa
Ko nani ibanuje Re

3 mp L‘oganjo fese elomi,


Eni kanu nsokun n‘n eje.
p Sibe, en‘ t‘o wole l‘anu
Olorun ko je d‘ehin Ko

4 mp Oganjo gan; lati papa


F A ngb‘orin awon angeli.
cr Orin titun t‘a ko gbo ri
p L‘o tu Olugbala l‘ara
Amin.

298 L.M.
0 si wifun mi pe, O pari.
Emi ni Alfa ati Omega, Ipinlese
ati opin. Ifi. 21:6.

1 P ―O pari‖ l‘Olugbala ke,


pp O te ori ba, O si ku,
cr ―O pari‖ Ire ije pin;
f O ti jagun! O si segun.

2 mf ―O pari‖! gbogb‘ase orun


Ati asotele ‘gbani
L‘a mu se b‘ati so tele
N‘nu Krist‘ Olugbala aye.

3 mf ―O pari‖ Igbe iku yi


Y‘o s‘etutu f‘ese gbogbo,
Opo y‘o si ri igbala
Nipa emi ‘kehin Jesu.

4 mf ―O pari‖ k‘iro ayo yi


Ka gbogbo orile-ede;
―O pari!‖ k‘isegun na de,
K‘o dapo mo orin t‘oke.
Amin.

299 C.M
Sa ro ti Eniti O farada iru isoro-odi
yi lati odo awon elese si ara
won. Heb. 12:3.

1 mp Wo Olugbala araye
T‘ A kan m‘agbelebu!
Ifena ti po to, t‘O fe
Lati wa ku fun O!
2 p Gbo‘kerora Re! bo ti ke,
Isele nla-nla se;
cr Ikele tempil pin me j i,
pp Okuta re sisan.

3 mf Opari! Ati san‘gbese,


di O ke, ‗ ‗gba emi Mi‖;
Wo b‘O ti te ori Re ba,
pp O te ba O si ku.

4 cr Laipe, y‘O ja ide iku


Ogo Re y‘o si tan;
F Olugbala, ko Ji ‘rora;
ff Tabi ‘fe bi Tire.
Amin.

300 8.7.8.7.D.
On o ru aisedede won wonni.
Isa. 53:11.

1 mp W ‘Olori Alufa giga,


B‘o ti gbe ebe wa LO;
p L‘ogba O fikedun wole
O feru d‘oju bole;
Angeli fidamu duro
Lati ri Eleda be;
cr Awa o ha wa l‘aigb‘ogbe,
T‘a mo pe ‘tori wa ni?

2 mf Kiki eje Jesu nikan


L‘o le yi okan pada;
On lo le gba wa n‘nu ebi,
On lo le m‘okan wa ro;
Ofin at‘ikilo ko to,
Won ko si le nikan se;
cr Ero yi lo m‘okan ro;
Oluwa ku dipo mi;

3 mf Jesu, gbogbo itunu wa,


Lat‘ odo Re lo ti nwa;
cr Ife, gbagbo, ‘reti, suru.'
Gbogbo re l‘eje Re ra;
F Lat‘ inu ekun Re l‘a ngba,
A ko da ohun kan ni;
L‘ofe n‘iwo nfi won tore
Fun awon t‘o s‘alaini.
Amin.

301 L.M.
Emi nsokun nitori nkan wonyi;
oju mi san omi sile. E. Jer. 1:16.

1 mp Ara, e wa ba mi s‘ofo;
E wa s‘odo Olugbala;
Wa, e je ka jumo s‘ofo;
p A kan Jesu m‘agbelebu.

2 mp Ko ha s‘omije l‘oju wa
Bi awon Ju ti nfi s‘efe?
A! e wo, b‘O ti teriba;
p A kan Jesu m‘agbelebu.

3 mp Emeje l‘O s‘ore ife,


p Idake wakati meta
L‘O fi ntoro anu f‘eyan
A kan Jesu m‘agbelebu.

4 cr Bu sekun, okan lile mi,


mp Ese at‘igberaga re
L‘o da Oluwa re l‘ebi;
p A kan Jesu m‘agbelebu.

5 Ibanuje at‘omije
Bere a ki o fi du o;
‘Banuje t‘O nf‘ ife Re han;
p A kan Jesu m‘agbelebu.

6 cr Ife Baba ese eda


N‘ihin Pa ri agbara Re
Ife l‘O si di asegun,
p A kan Olufe wa mo ‘gi.
Amin

302 6.5.6.5.
Eje Kristi iyebiye. I Pet. 1:19.

1 O go ni fun Jesu
p T‘O fi ‘rora nla
cr Ta eje Re fun mi
Lati iha Re.

2 f Mo r‘iye ailopin
Ninu eje na;
Iyonu Re sa po,
Ore Re ki tan!

3 f Ope ni titi lae


F‘eje ‘yebiye
T‘Ora aye pada
Kuro n‘nu egbe.
4 mf Eje Abel‘ nkigbe
Si orun f‘esan;
Sugbon eje Jesu nke
F Fun ‘dariji wa.

5 p Nigbati a bu won
Okan ese wa,
Satan, n‘idamu re
F‘eru sa jade.

6 f Nigbat‘ aye ba nyo,


T‘o n gbe ‗yin Re ga;
AWON ogun angel'
A ma f‘ayo gbe

7 f Nje egb'ohun yin ga,


Ki iro na dun!
ff Kikan l‘ohun Koto
Yin Od‘agutan.
Amin

303 C.M.
Nigbati won de ibi ti a npe ni
Agbari, nibe ni nwon gbe kan A
mo agbelebu. Lk. 23:33.

1 m O ke kan mbe jina rere,


L‘eyin odi ilu;
p Nibit‘ a kan Oluwa mo
cr Eni t‘O ku fun wa.

2 p A ko le mo, a ko le SO
B‘irora Re ti to!
cr Sugbon a mo pe ‘tori wa
L‘O se jiya nibe.

3 mf Oku k‘aleri‘dariji,
K‘ale huwa rere;
cr K‘ a si le d‘ orun nikeyin,
p Ni ‘toye eje Re

4 mf Ko tun s‘eni‘re miran mo


T‘o le sanwo ese!
cr Oun l‘O le silekun orun,
K‘o si gba wa sile.

5 f A! b‘ife Re ti sowon to;


O ye ka feran Re;'
K‘a si gbekele eje Re.
K‘a si se ife Re
Amin.

304 C.M
E duro nihinyi ki e si ma
Bami sona. Mat. 26: 38.

1 p Okun l‘ale tutu n'ile


Nibi Kristi wole;
p Ogun Re bi iro eje
Ninu ‘waya ija.

2 mf ―Baba gb‘ago kikoro yi


B‘O ba se ife Re,
Bi beko, emi o si mu
Ife Re nik‘ase.‖

3 Elese lo WO l‘agbala
Eje mimo wonni;
p O r‘eru ‘wuwo ni fun o
O si mu ‘po ‘rele.

4 KO lati gbe agbelebu,


Se ife ti Baba;
Nigba idanwo sun mo le
ff Ji, sora, gbadura.
Amin.

305 C.M.
Alabapin ninu iya Re. Fili. 3:10.

1 p Ki Jesu ha nikan jiya,


K‘araye lo l‘ofo?
p Iya mbe folukuluku
cr Iya si mbe fun mi.

2 mf Ayo awon mimo tito


T‘won banuje l‘aye;
Nisiyi won ngbe ‘nu ife
F Ati ayo pipe.

3 p Em‘o ru agbelebu mi
Tit‘iku y‘o gba mi,
mf ‘Gbana un o lo ‘le lo d‘ade
Tor‘ ade mbe fun mi.
Amin.

306 8.7.8.7.4.7.
0 pari. Jn. 19:30.
1 mf Egb‘ohun ife at‘anu
Ti ndun l‘oke Kalfuri!
Wo! o san awon apata!
O mi ‘le, o m‘orun su!
p― Otipari‖, ―Otipari‖
Gbo b‘Olugbala ti nke.

2 mp ―Oti pari‖, b‘otidun to.


Ohun t‘oro wonyi wi,
Ibukun orun l‘ainiye
Ti odo Krist‘ san si wa;
―Otipari‖, ―Otipari‖
p E ranti oro wonyi.

3 f Ise igbala wa pari,


Jesu ti mu ofin se!
O pari nkan t'Olorun wi,
Awa ki o ka‘kusi;
p ―Otipari‖, ―Otipari‖,
Ayanfe, ‘tunu l‘eyi.

4 f E tun harpu yin se Seraf‘


Lati korin ogo Re;
Araye at‘ara orun
ff Yin oruko Imanuel‘
p ―O ti pari‖ ―o ti pari‖
Ogo fun Od'agutan.
Amin.

307 6.6.6.6.6.6.
O fi emi Re lelefun awon
agutan Re. Jn. 10:11.

1 O f ara Re fun mi,


p O ku nitori mi,
cr K‘O le ra mi pada,
Ki nle jinde n‘n‘ oku,
O fara Re fun mi,
p Ki l‘emi se fun O?

2 O F‘OJO aye Re,


Se wahala fun mi;
Ki emi ba le mo
Adun ayeraye,
O L‘OPO odun fun mi
Mo lo kan fun O bi?

3 Ile ti Baba Re
At‘ite ogo Re
O fi sile w‘aye
O d‘alarinkiri
O fi ‘le ‘tori mi,
Mo fi nkan fun O bi?

4 p O jiya po fun mi,


Ti enu ko le SO
O jijakadi nla
cr ‘Tori igbala mi,
O jiya po fun mi,
mp Mo jiya fun O bi?

5 f O mu igbala nla
Lat‘ile Baba Re
Wa lati fifun mi,
O si dariji mi.
O m‘ebun wa fun mi
Kin‘ mo mu wa fun O?

6 mf Uno f ara mi fun O,


Un o f‘aye mi sin 0.
Uno d‘iju si aye,
Uno wo ohun t‘orun,
Mo f‘ohun gbogbo mi
F‘Oluwa, Oba mi.
Amin.

308 C.M;
Wo Odo-agutan Olorun. . Jn. 1:36

1 mf W o Od‘agutan ti o ru
Eru re lor‘ igi;
O kulati da igbekun,
p O t‘eje Re fun o

2 mp W‘Olugbala tit‘ iran na


Y‘o fi fa okan re;
p Fi omije rin ese Re,
Ma kuro lodo Re.

3 cr Wo, tit‘ ife Re yio fi


Joba lor‘okan re,
Tit‘ agbara Re y‘o fi han
Lor‘ ara on emi.

4 mf Wo O bo ti nsare ije
Ore re titi lae;
f Y‘o pari ise t‘O bere,
Or‘ofe y‘o j‘ogo.
Amin.
309 8.7.8.7.
Koju si Mi, ao si gba nyin la.
Isa. 45:22.

1 mf Wakati didun ni fun mi


p Ni wiwo agbelebu;
cr Nibe, Jesu fun mi n‘iye,
Ilera at‘alafia.

2 mp Nihin l‘emi o gbe joko


Lati wo isun eje
Eyiti y‘o we okan mi
K‘Olorun ba le gba mi

3 mf Niwaju agbelebu Re,


L‘emi ba buruburu
‘Gbat‘ emi ha ri yonu nla
T‘o farahan l‘oju Re

4 Ife ati omije mi


Ni uno fi we ese Re;
cr ‘Tori mo mo pe iku Re
Y‘o mu iye wa fun mi.

5 mf Oluwa, jo gba ebe mi,


cr Se okan mi ni Tire,
f Tit‘ emi o fi r‘igbala
At‘oju Re nin‘ogo.
Amin.

310 L.M.
Sugbon ki a mase ri pe, emi nsogo
Biko se ninu agbelebu Jesu Kristi
Oluwa wa. Gal. 6:14.

1 mf ‗Gbati mo ri agbelebu
Ti a kan Oba Ogo mo
Mo ka gbogbo oro s‘ofo
Mo kegan gbogbo ogo mi.

2 cr K‘a mase gbo pe mo nhale


B‘o ye n‘iku Oluwa mi
Gbogbo nkan asan ti mo fe
Mo da sile fun eje Re

3 p Wo, lat‘ ori, OWO, ese


B‘ikanu at‘ife ti nsan;
cr ‘Banuje at‘ ife papo,
A fegun se ade ogo
4 mf Gbogbo aye ‘baje t‘emi.
Ebun abere ni fun mi;
F Ife nla ti nyanilenu
Gba gbogbo okan, emi mi.
Amin.

311 S.M.
Opari. Jn. 19:30.
1 mp Ife l‘o to bayi!
Ohun gbogbo pari,
Oti pari gbogbo ise
T‘O tori re w‘aye.

2 Ohun ti Baba fe
Ni Jesu ti se tan;
p Wahala ati iya Re
cr Mu iwe mimo se

3 Ko s‘irora wa kan
Ti Jesu ko je ri;
Gbogbo edun at‘aniyan
L'okan Re si ti mo

4 L‘ori t‘a f‘egun de,


At‘okan Re mimo
L‘a ko gbogbo ese wa le
cr K‘O ba le wo wa san.

5 p Ife l‘omu k‘O ku


Fun emi otosi,
cr ‘Wo etutu fese gbogbo,
Mo figbagbo ro mo

6 mf Nigba aini gbogbo,


Ati n‘ite ‘dajo
cr Jesu, ododo Re nikan
Ni igbekele mi.

7 mf Jo, sise ninu mi,


Bi O ti se fun mi,
cr Si je ki ife mi si O
Ma fi ore Re han.
Amin.

312 5.5.11.D.
Ko ha kan nyin bi, gbogbo
enyin ti nkoja? E. Jer. 1:12.

1 mf E yin ti nkoja,
Ya s‘odo Jesu;
mp O ha s‘asan fun yin bi Jesu-ba ku;
Olurapada,
Onigbowo yin,
p Wa, wo bi ‘banuje kan ri bi Tire.

2 cr Eje Re s‘etu
Fun ese t‘eda,
Mp Baba se Omo Re n‘ise nitori yin,
Oluwa, ni‘jo
Ti ‗binu Re ru,
K‘ese yin l‘Od‘agunta t‘O ko won lo

3 mf O duro fun wa,


E wa je ‘pe Re
E fi ‘yanu wole lab‘agbelebu!
E gb‘oju woke,
Bi Jesu ti nke,
p O jiya laibohun; Eni aiku ku.

4 mf O s‘etu f‘ese
Ti ki se Tire
O san igbese yin, O sise fun yin;
Gbogbo yin le pin N‘nu alafia Re,
mp Eni bebe pe; ―Baba mi dariji'‘

5 mf O bebe fun wa Lor‘agbelebu,


Adura Re gba, elese domnira;
Emi elese
T‘o gba Jesu gbo,
Mo wa gba ‗fiji t‘O Ki o fi du mi.

6 mp Ma toro ‘fiji;
Nitori mo je
Elese t‘o gba oruko Jesu gbo
O ra or‘ofe
Ti mo gba mora;
Baba, Iwo mo pe O ku dipo mi.

7 cr Iku Re setu;
‘Wo Alagbawi mi
Gbo b‘eje t‘a ta ‘le ti mbebe fun mi;
O ra mi pada,
‘Gba t‘O ku lor‘igi;
F Emi Re t‘O fi lele da mi lare.
Amin.

313 C.M. & Ref.


Wo o ki e si ri bi ibanuje
kan ba wa. Bi ibanuje mi. E- Jer. 1:12.
1 mf Olugbala mi ha gb‘ogbe!
Oba Ogo ha ku!
On ha je fara Re rubo
F‘eni ile b‘emi.
Ran mi lowo Olugbala,
Lati fe O toto
‘Gbat‘O ba de ijoba Re
Oluwa ranti mi.

2 mp Iha se ese ti mo da
L‘o gbe ko s‘or'igi?
Anu at‘ore yi ma po
cr Ife yi rekoja!

3 mp O ye k‘orun foju pamo,


K‘o b‘ogo re mole,
‘Gbati Kristi Eleda ku
Fun ese eda Re

4 mp Be l‘o ye k‘oju ko ti mi
‘Gba mo r‘agbelebu,
O ye k‘okan mi kun f!ope
Oju mi f omije.

5 mf Sugbon omije ko le san


‘Gbese ‘feti mo je;
Mo fara mi f‘Oluwa mi
Eyi ni mo le se.
Amin.

314 7.7.7.6.
Baba Dariji won nitori ti n won
Ko mo ohun ti nwon nse Lk. 23:34.

1 mf ‗Wo t‘O mbebe f‘ota Re,


L‘ori ‘gi agbelebu;
Wipe, ―Fiji won, Baba‖,
p Jesu, sanu fun wa.

2 mf Jesu jo bebe fun wa,


Fun ese wa ‘gba gbogbo,
Ako mo ohun t‘a se;
p Jesu, sanu fun wa.

3 mf Je k‘awa ti nwa anu


Dabi Re l‘okan n‘iwa,
Gbat‘ a ba se wa n‘ibi;
p Jesu, sanu fun wa.

LONI NI IWO O WA PELU


MINI PARADISE Lk. 23:43.

4 mf Jesu,‘Wot‘O gbo aro


Ole t‘o ku l‘egbe Re.
T‘O si mu d‘orun rere
p Jesu, sanu fun wa.

5 mf Ninu ebi ese wa,


Je k‘atoro anu Re;
K‘a ma pe oruko Re,
p Jesu, sanu fun wa.

6 mp Ranti awa t‘o nrahun,


T‘a nwo agbelebu Re,
F‘ireti mimo fun wa,
p Jesu, sanu fun wa.

OBIRIN, WO OMO RE:


OMO WO IYA RE. Jn. 19:26 & 27

7 mf ‘Wo t‘O fel‘afedopin


Iya Re t‘o nkanu Re
Ati ore Re owon;
p Jesu, sanu fun wa.

8 mf Jeka pin n‘nu iya Re,


Ka ma ko iku fun O,
cr Jek‘ari‘toju Re gba;
cr Jesu, sanu fun wa.

9 f Ki gbogbo awa Tire,


Je omo ile kanna;
cr Tori Re ka fe ‘ra wa;
p Jesu, sanu fun wa.

OLORUN MI, OLORUN MI,


ESE TI IWO FI KO MI SILE?
Mat. 27:46.

10 mf Jesu ‘Wo ti eru mba,


‘Gbat‘ O si ku ‘WO nikan
cr Ti okunkun su bo O,
p Jesu, sanu fun wa

11 mf ‘Gbati a ba npe lasan,


T‘ireti wa si jina,
N‘nu ok un na di wa mu.
p Jesu, sanu fun wa

12 mf B‘o dabi Baba ko gbo,


B‘o dabi ‘mole ko si,
Jeka f‘igbagbo ri O.
p Jesu, sanu fun WA

ORUNGBE NGBE MI. Jn.19:28

13 mf Jesu, ninu ongbe Re


Ni ori agbelebu,
cr ‘WO ti O fe wa sibe,
p Jesu, sanu fun wa.

14 mf Ma k‘ongbe fun wa sibe,


Sise mimo l‘ara wa;
Te ife Re na l‘orun;
p Jesu, sanu fun wa.

15 mj Jeka kongbe ife Re


Ma s‘amona wa titi,
Sibi omi iye ni,
p Jesu, sanu fun wa.

O PARI Jn. 19:30.

16 mf Jesu Olurapada,
‘Wo t‘Ose‘fe Baba Re,
T‘O si jiya tori wa
p Jesu, sanu fun wa.

17 mf Gba wa l‘OJO idamu,


Se Oluranlowo wa,
Lati ma t‘ona mimo,
p Jesu, sanu fun wa.

18 mf F‘imole Re s‘ona wa
Ti yo ma tan titi lae,
Tit‘ ao fi de odo Re;
p Jesu, sanu fun wa

BABA, LI OWO RE; NI MO


FI EMI MI LE. Lk 23.46

19 mf Jesu, gbogbo ise Re,


Gbogbo idamu Re pin,
F O jow‘ emi Re lowo
p Jesu sanu fun wa

20 mp ‘Gba ti ‘ku bu de ba wa,


Gba wa lowo ota wa,
F Yo wa ni wakati na,
p Jesu, sanu fun wa.
21 Ki iju at‘iye Re,
Mu ore ofe ba wa,
TI yio mu wa doke,
p Jesu, sanu fun Wa
Amin

315 10.9
ITAN ORI AGBELEBU
Won o ma wo eniti a gun li oko. Jn. 19:37

GETSEMANE

1 p N 'iwaya ‘Jakadi, / On nikan nja,


O n fe iranlowo / sugbon ko ri.
2 B‘osupa ti nwo / l‘or‘oke Olif,
Adura tani ngoke / l‘oru yi?
3 Eje wo l‘eyi ti nro bi ojo,
Lat‘okan Re wa, ―Eni ‘banuje‖
4 Irora ailese / mbe l‘oju Re,
Ojiya ti mbebe, tan‘ Iwo?

QNA IKANU
1 mp Gbo b‘O ti mba o so / ‘ro lokan re
―Omo ti mo ku fun / tele mi‖
2 ―Ki nma m‘ago ti/Baba fun mi bi
‘Gbati mimu re je‖ / ‘gbala re
3 ― A lu, a tuto si, / a fi s‘efe;
A na, a si de / l‘ade egun.
4 ―Mo nlo si Golgota/ nibe, Uno ku,
cr ‘Tor‘ ife Misi o/Emi ni.

ORO MEJE LORI AGBELEBU

1 mp A kan mo ‘gi esin, / ko ke rora,


O r‘eru wa, / ‘Tire ko.
2 ‘Wo orun mi ole/ wo okun bi?
Oro wo lo nte / ‘nu Re wa ni
3 ―Baba dariji won/l‘adura Re,
cr Baba si gbo, bi/‘ti ma gbo‘ri.
4 Gbo bi ole ni ti / ntoro anu;
mf On se 'leri Pa / radise fun.
5 Ibatan at‘ore / rogba yika,
Maria on Magdalen ropin re.
6 Meji ninu won di / tiya t‘omo,
Okan t‘oro Re / ti so d‘okan.
7 p Okunkun bo ile / osan d‘oru,
Iseju koja b‘ / odun pipo.
8 pp Gbo ‘gbe ‘rora lat‘ i /nu okun na
―Baba, ‘Wo ko mi / sile ese?‖
9 A! ikosile nla / iku egun!
Igbe kil‘eyi, / ―Ongbe ngbe Mi‖!
10 cr Gbo ―O ti pari‖ / Ijakadi pin,
Iku at‘ipoku, / a se won.
11 p ―Baba, gba emi mi,‖ / L‘o wi keyin,
Krist‘ Oluwa iye / O si ku.
IKESI
1 mp ―O mo ‘rora mi ti / mo feje ra,
Mo gba o low‘esu, f‘ Olorun;
2 cr ―Wa alare, wa f‘ori / laya mi,
Sapamo sodo mi, / ko simi.
3 mf ―Wa sodo Baba mi, / wa laiberu.
Alagbawi re, / wa nitosi.
4 ―Wa mu ninu ore / ofe emi;
Emi ni ini re / ‘Wo t‘emi.

IDAHUN
1 mf M o fara mi fun O / Oluwa mi,
Sa fi ‘fe Re ‘yebiye fun mi.
2 mf Gbogb‘ohun ti mo ni / t‘ara t‘okan
Nko je fi du O / gba gbogno re
3 cr Sa ba mi gbe dopin / Oluwa mi,
Jesu, Olugbala / Oluwa mi
4 B‘a koko Re ba de / Je ki nyin O
Yin O nile Re/ titi laelae
Amin.

316 C.M. & Ref.


On si tifi eje agbelebu Re se ilaja.
Kol, 1:20.

1 mp O se! Olugbala mi ta
p ‘Je Re sile. O ku,
Nje O je fori mimo na
Fun kokoro b‘emi.
mf Nibi agbelebu ni mo ko ri ‘mole.
Nibe, eru okan mi si fo lo;
Nibe, nipa igbagbo. mo riran,
F N‘siyi, mo wa l‘alafia titi.

2 mp Nje ‘tor‘ese ti mo ti da
L‘O se jiya oro,
Anu at‘ore ofe yi
Ko se diwon rara.

3 p O to k‘orun ko s‘okunkun,
Ko f‘ogo re pamo;
Nigba Kristi Eleda nla ku
Fese awa eda.
4 cr Sugbon ‘banuje ko le san
‘Gbese ‘feti mo je,
mf Kristi mo f‘ara mi fun O
Eyi ni mo le se.
Amin.

317 7.7.7.8.
A kegan Re, a si koo lodo awon
eniyan. Isa. 53:3.

1 E ni ‘kanu! - oruko
cr T‘a npe Omo Olorun;
f T‘O wa gba elese la!
ff Aleluya! Olugbala!

2 mf O farada eleya,
Ada lebi nipomi!
Eje Re setu fun mi
ff Aleluya! Olugbala!

3 cr Oto s‘elese ni wa;


Alailabawon li On:
Nje loto lO setutu?
ff Aleluya! Olugbala!

4 mp A gbe ko sori igi,


p Okepe, Oti pari!
A gbe ga lorun n‘isiyi:
Aleluya! Olugbala!

5 mf ‘Gbat‘ Oba Ogo b'a de,


‘Lati m‘eni Re re ‘le
Ao ko orin yi lotun
ff Aleluya! Olugbala!
Amin.

318 8.8.8.8.8.8.
Nigbati awaje elese, Kristi ku fun wa. Rom. 5:8.

1 mf O ha le je pe mo n‘ipin
Ninu eje Olugbala?
P‘O ku f‘emi t‘O da loro,
T‘o lepa Re doju iku?
f Ife‘yanu! ehati se
Ti ‘Wo Olorun ku fun mi?

2 p Ohun ‘jinle! Olorun ku!


Tani mo odi ete Re?
Lasan l‘angeli ta ko da
Nfe mo, ‘jinle ife mimo!
Anu sa ni! k‘aye juba,
Ki angeli ma wadi mo.

3 mf O f‘ite Baba Re sile,


Ore-ofe Re ko lopin!
O bo gbogb‘ ogo Re sile,
O ku fun ‘ran omo Adam,
Anu sa ni, laini iwon;
F L‘O wa mi ri, Olorun mi.

4 mf O pe ta ti de emi mi
Sinsin l‘o kun ewon see;
Oju Re tan ‘mole iye,
Mo taji, tubu si mole;
Ewon mi bo, mo d‘ominira
Mo dide, mo si nto leyin.

5 p Emi ko jaya ebi mo;


Temi ni Krist, patapata!
Mf Mo ye ninu Olori mi,
A f‘ododo orun WO mi,
N‘igboya, mo sunmo ite,
Mo gba ade, lagbara Kristi.
Amin.

319 L.M.
Kristi Jesu, eniti Olorun fi fe Ogbon ati
ododo, ati isodi mimo ati idandefun wa. IKor. 1:30.

1 mf Jesu, eje ododo Re


Li ewa ati aso mi;
Bi mba WO won, b‘aye ngbina
F Uno f ayo gb‘ori mi soke.

2 f Uno ni ‘gboya l‘ojo ‘dajo;


Tani ‘ba ka si mi lorun?
A we mi mo patapata
Kuro l‘ese, l‘eru, l‘ebi.

3 mp Alailegan Od‘agutan
T‘O t‘okan-aya Baba wa,
T‘O ku lati setu fun mi,
Ni mo yan ni Olorun mi.

4 mp Oluwa, emi gbagbo pe


Eje Re nib‘ite-anu
Ti nsipe lae fun elese
p L‘a ta sile fun emi mi.

5 mf Oluwa, mo si gbagbo pe
B‘elese Po bi iyanrin,
‘Wo ti ra gbogbo wpo pada,
cr ‘Wo ti setu fun gbogbo won.

6 mf ‘Gba mba jinde ninu oku


Lati gba ‘bugbe mi lorun,
Eyi ni yo je ebe mi,
p Jesu w‘aye, O ku fun mi.
Amin.

320 9.9.9.9.& Ref.


Nigbati emi ba ri eje na,
emi o re nyin koja. Eks. 12:13.

1 p K risti ku l‘ori agbelebu,


O ku fun igbese elese
F‘e j‘Odagutan we okan re,
On yoo si re yin koja lo.
mp ‘Gba to ba ri eje,
‘Gba to ba ri eje,
‘Gba to ba ri eje,
0n yio re yin koja lo.

2 mf Jesu y‘O gbeni to buru ju,


Yio mu gbogbo ileri se,
We n‘nu orisun iwenumo,
On yio si re yin koja lo

3 mp Idajo mbp fun gbogbo aye,


Olukuluku y‘o gba ere,
F‘eje ‘wenumo se abo re,
On yio si re yin koja lo.

4 mf A! anu at‘ife ailopin,


A! inu rere at‘otito,
Wa alafia n‘nu eje na,
On yio si re yin koja lo.
Amin.

321 11.11.11.77. & Ref.


Li ojo ti mo kepe, iwo da mi lohun,
Iwo sifi ipa mu mi lara le li okan. OD. 138:3.

1 mf Mo nko ‘rin ti
Eni t‘o gb‘emi mi la,
Mo ro m‘Ore na to so mi di pipe,
Ni ‘daniloju pe nigba mba dele
Lojukoju ni uno ri.
F Lojukoju ni uno ri,
Mo gbekel‘ or‘ofe Re,
Nipari ‘rin ajo mi,
Lojukoju ni un o ri.

2 cr Mo ngbe ‘nu eni


Kanna ti mo njuba
Lojojo ni mo si nrohin ore Re,
Pe lehin gbogbo idanwo aye yi,
Lojukoju ni un o ri.

3 mf Mo ngbe ninu ‘mole orun ife Re,


Mo si nka fun ojo ‘kore ti oke,
Ti mo ba si je ojo tito nihin,
Lojukoju ni un o ri.

4 f Niwaju Re, mo nri alafia pipe,


Itan Re mu ‘nu gbogbo eniyan dun,
Ni ‘daniloju pe nile wa loke
Lojukoju ni un o ri.
Amin.

322 8.8.8.6.D.
Olufe mi ni temi, emi si ni Tire.
O. Sol. 2:16.

1 mf Ife ti Jesu ni si mi,


To jiya lor‘agbelebu,
Ki mba le d‘eni rapada
Ju ‘yi t‘ahon le SO.
ff Ife Re si mi po jojo
Ju ‘yi ti mo le rohin lo,
Ife ti Jesu ni si mi
Ju ‘yi t‘ahon le SO

2 p Iya kikoro ti o je
At‘ade egun t‘a fi de
Ki mba le ye titi aye
Ju ‘yi t‘ahon le SO

3 mf Ibale okan t‘O nfun mi,


Ebe t‘O mbe fun mi loke,
Ore t‘eje Re nse fun mi
Ju ‘yi t‘ahon le SO

4 f Ayo ti mo ni ninu mi,


Isimi at‘alafia;
Ireti pe O tun mbo wa
Ju‘yi t‘ahon le SO.
Amin.

323 L.M.
O si ti se alafia nipa eje agbelebu Re. Kol. 1:20.

1 mf Agbelebu ni ere mi,


Nibe ni a rubo fun mi;
Nibe l‘a kan Oluwa mo,
Nibe l‘Olugbala mi ku.

2 mf Kinio le fa okan Re
Lati teri gba iya mi?
Aimohun na daju l‘o se
p T‘okan mi tutu be si O

3 mf Aifohun na oju ti mi
Niwaju Jesu mimo mi,
p T'O taje Re sile fun mi,
Tori o fe mi l‘afeju.
Amin.

324 C. M,
Awon wonyi ni not Odo-aguntan
Lehin, nibikibi ti nre. Ifi 14:4

1 mf E je k‘a to Jesu wa lo,


Ni agbala nla ni,
Nibiti o NLO gbadura,
p Nibit‘ o nlo kanu

2 K‘a wo b‘O ti dojubole,


p T‘O nmi imi edun,
Eru ese wa l‘O gberu.
Ese gbogbo aye.

3 Elese, wo Oluwa re,


Eni mimo julo;
Nitori re ni Baba ko O,
Aye si d‘ota Re.

4 mf IWO o ha wo laironu,
Lai k‘ese re sile?
p Ojo idariji nkoja,
Ojo igbala nlo.
Amin.

325 6.6.6.6.8.8.
Ko si nihin yi, sugbon O jinde. Lk. 24:6.

1 mf Pelu iye didan


L‘oro kutukutu,
L‘angeli sokale,
cr O y‘okuta kuro.
F E jumogb‘ohun yin
E yin Oluwa t‘O Jinde

2 mf ‘Gbat‘ awon oluso


Ri iran eru na
Won subu lojiji,
Won si dabi oku.

3 cr O nde n‘isu oku,


Oju eda ko ri;
O segun Iboji,
Oluwa gbogb' aye

4 cr Eyin omo ‘mole,


E nde pel‘ Oluwa;
Wo bi irawo Re,
Ti ntan l‘oju orun

5 mp Fi ohun atijo
Sile ninu ‘boji,
A sin yin n‘nu Jesu,
Eba jinde loni.

6 A yin O Oluwa,
Pelu agbara wa
N‘tori a je Tire,
‘Wo si je tiwa lae.
Amin.

326 S.M
Nwipe, Oluwa jinde, nitotO,
O si tifi ara han fun Simoni. Lk. 24:34.

1 f Oluwa ji loto
Ise ‗gbala pari,
A tu awon onde sile,
A si s‘ete iku

2 f ―Oluwa ji loto‖
Esu so tire nu,
Awon t‘ara ji pelu Re
Lati joba laelae.

3 f ―Oluwa ji loto‖
O mbe, ko ni ku mo,
O mbe, lati be f‘elese
Ti O ru egun won

4 f ―Oluwa ji loto‖
Eyin Angeli gbo
S‘agbala orun, e sare,
Mu ‗hin ayo na lo.

5 ff E mu duru wura
K‘e si te ‘rin didun!
Eyin egbe orun dapo
Lati k‘ajinde Re
Amin.

327 8.7.8.3
A woran re yio te mi lorun nigba
ti mo baji OD. 17:15.

1 f L ‘ oruwo ojo ajinde,


T‘ara t‘okan yo pade,
Ekun, ‘kanu on irora
Yo dopin. .

2 p Nihin, won ko le sai pinya


Ki ara ba le simi
Ko si fi idake roro
Sun fonfon.

3 Fun ‘gba die ara are yi


La gbe sibi ‘simi re
cr Titi di imole oro
Ajinde.

4 mf Sugbon okan to ns‘asaro


To si ngbadura kikan
Yo bu s‘orin ayo lojo
Ajinde.

5 mf Ara at‘okan yo dapo,


Ipinya ko ni si mo;
cr Won o ji l‘aworan
Krist‘ ni ‘Telorun.

6 f A! ewa na at‘ayo na
Yo ti po to lAjinde!
Yo duro borun ataye
Ba fo lo.

7 mf L‘oro ojo ajinde wa


'Boji yo m‘oku re wa;
Baba, iya, omo, ara Yo pade.

8 Si ‘dapo ti o dun bayi


di Jesu masai ka wa ye;
p N‘nu‘ku,‘dajo, kalero m‘a Gbelebu.
Amin.

328 6.6.6..6.8.8
IWO ti di igbekun ni igbekun lo
OD. 68:18.

1 f Oro ayo nade,


Olugbala bori;
cr O fi ‘boji sile
Bi Olodumare,
ff A d‘igbekun ni ‘gbekun lo,
Jesu t‘O ku di alaye.

2 p Onigbowo wa ku,
mf Tani to fi wa sun?
Baba da wa lare,
Tal‘o to da ebi?

3 mf Kristi ti san gbese,


Ise ogo pari;
O ti ran wa lowo,
O ti ba wa segun.
Amin.

329 7.8.7.8.4.
Kiyesi i, Emi mbe laye titi lae A min.
Ifi. 1:18.

1 f J esu ye titi aye,


Eru iku ko ba mi mo;
Jesu ye; nitorina
Isa oku ko n‘ipa mo — Aleluya.

2 mf Jesu ye, lat‘ oni lo,


Iku je ona si iye;
Eyi y‘o je ‘tunu wa
‘Gbat‘ akoko iku ba de — Aleluya.

3 mp Jesu ye; fun wa lo ku,


Nje Tire, ni a o ma se;
cr A o f okan funfunsin,
A o f ogo fOlugbala — Aleluya.

4 Jesu ye; eyi daju,


Iku at‘ipa okunkun
Ki yo le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu — Aleluya.

5 Jesu ye; gbogbo ‘joba


L‘orun, li aye, di Tire;
mf Eje kia ma tele,
cr Ki a le joba pelu Re— Aleluya.
Amin

330 7.6.7.6.D.
Wo o, Jesu pade won, O wipe Alafia Mat. 28:9.

1 f Eyi l‘ojo ajinde,


Wi kakiri aye;
Irekoja didun ni,
T‘Olorun Olore;
Lat‘ Inu iku s‘iye,
Lat'aye si orun,
ff Ni Krist‘ ti mu wa koja,
Pel‘ orin isegun

2 mf Oluwa we okan wa,


Ko ba le mo toto;
Ka ba le ri Oluwa
N‘nu ‘mole ajinde;
cr Ka si feti sohun Re
Ti ndun lohunjeje,
Pe ―Alafia fun yin‖
Ka nde, ka si tele.

3 f Eyin orun, bu sayo


K‘aye bere gberin;
Ki gbogbo aye yika
Dapo lati gberin;
Eda nla ati wewe,
E gbohun yin soke,
ff ‘Tori Kristi ti jinde,
Ayo wa ki yo pin.
Amin.

331 11.11.11.11. & Ref.


Mo si ni kokoro iku ati ti ipo oku Ifi. 1:18.

1 f K abo ojo rere l‘ao ma wi titi;


Asete ku loni orun di tiwa,
‘WO oku d‘alaye, Oba tit‘aye,
Gbogb‘ eda Re, Jesu, ni nwon njuba Re.
ff ―Kabo ojo rere,‖ lao ma wi titi
A sete ku loni, orun di ti wa.

2 mf Eleda, Oluwa, Emi alaye!


Lat‘orun l‘O ti b‘ojuwo ‘sina wa;
Om‘Olorun papa ni ‘Wo tile se,
K‘O ba le gba wa la; O di eniyan.
3 mf ‘WO Oluwa iye, O wa to ‘ku wo;
Lati fipa Re han, O sun n‘iboji;
Wa, Eni Oloto, Si m‘oro Re se,
OJO keta Re de, jinde Oluwa!

4 mf Tu igbekun sile, t‘esu de l‘ewon,


Awon to si subu, jo gbe won dide.
F‘oju rere Re han, je k‘aye riran,
Tun mu mole wa de, ‘WO sa ni ‘Mole.
Amin.

332 D.C.M.
Ji ohun elo orin mimo ati duru
emi tikara mi yio si ji ni kutukutu. OD. 108:2.

1 f Ji, ji okan ayo ji, ji.


Oluwa re jinde
LO ‘boji Re, ko si mura
Okan ati korin;
Gbogbo eda lo si tiji,
Ti won nkorin didun,
Itanna ‘ kini to ko tan
Leba odo lo hu.

2 mf Isudede aye yo lo
Lojo ajinde yi;
Iku ko si mo ninu
Kristi Iboji ko n‘ipa
F Ninu Kristi la nwa, ta nsun,
T‘a nji, ta si ndide;
p Omije t‘iku mu ba wa
cr Ni Jesu yo nu nu.

3 f Ki gbogbo eye at‘igi


At‘itanna ti ntan,
Ki won SO ti isegun Re
Ati t‘ajinde Re,
Papa, e gb‘ohun yin soke
E bu sorin ayo,
Eyin oke, e si gberin
Wipe, ―Iku ti ku‖

4 ff Okan ayo, eji, e wa


Oluwa t'O jinde.
E yo ninu ajinde Re,
K‘oro Re tu yin n‘nu;
E gb‘ohun yin soke, k‘eyin
Eni t'O ji dide;
L‘ohun kan ni ka gberin pe
―Jesu jinde fun mi‖.
Amin.

333 8.8.3.4.
E korin titun si Oluwa; nitori
O ti se ohun iyanu. OD. 98:1.

ff ALELUYA, ALELUYA, ALELUYA!

1 f Ija d‘opin, ogun sitan,


Olugbala jagun molu,
ff Orin ayo lao ma ko; — Aleluya!

2 f Gbogbo ipa n‘iku ti lo,


Sugbon Kristi fogun re ka;
ff Aye! e ho iho ayo; — Aleiuya!

3 mf Ojo meta na ti koja;


cr O jinde kuro nin‘oku;
ff E fogo fun Oluwa wa —Aleluya!

4 f O d‘ewon orun apadi,


O silekun orun sile,
ff E korin iyin ‘segun Re — Aleluya!

5 p Jesu, nipa iya t‘O je


mf Gba wa lowo oro iku,
cr K‘a le ye, ka si ma yin 0 - Aleluya
Amin.

334 1.1.1.1. & Aleluya


Kristi ti jinde Mk. 16:6.

1 f K rist‘ Oluwa ji loni: - Aleluya!


Eda at‘Angeli nwi: - Aleluya!
Gb‘ayo at‘isegun ga - Aleluya!
K‘orun at‘aye gberin - Aleluya!

2 mf Ise ti idande tan: - Aleluya!


O jija, O ti segun - Aleluya!
Wo sisu orun koja: - Aleluya!
cr Ko wo sinu eje mo - Aleluya!

3 mf Lasan n‘iso at‘ami, - Aleluya!


F Krist‘ wo orun apadi - Aleluya!
Lasan l‘agbara iku - Aleluya!
Kristi si Paradise - Aleluya!

4 f O tun wa, Oba Ogo - Aleluya!


F ―Iku, itani re da‖ - Aleluya!
P L‘ekan l‘O ku, k‘O gba wa - Aleluya!
―Boji isegun Re da?‖ - Aleluya!

5 f E ja kawa goke lo - Aleluya!


Sodo Kristi, Ori wa, - Aleluya!
A sa jinde pelu Re: - Aleluya!
Cr Bi a ti ku pelu Re - Aleluya!

335 8.7.8.7,D.
Eniti O tun wa bi sinu ireti
aye nipa ajinde Jesu. I Pet. 1:3.

1 f Aleluya, Aleluya,
E gbe ohun ayo ga,
E ko orin inu didun
K‘e si yin Olorun wa;
p Eni t‘a kan m‘agbelebu
T‘O jiya fun ese wa,
ff Jesu Kristi, Oba Ogo
Jinde kuro n‘nu oku.

2 f Irin idabu se kuro,


Kristi ku, O si tun ye;
O mu iye ati aiku
Wa loro Ajinde Re;
Krist‘ ti segun, awa segun
Nipa agbara nla Re
ff Awa o jinde pelu Re
A o ba wo ‘nu ogo.

3 mf Kristi jinde, akobi ni


Ninu awon t‘o ti sun;
Awon yi ni y‘o ji dide
Ni abo Re ekeji;
Ikore ti won ti pon tan,
Won nreti Olukore,
Eni ti y‘o mu won kuro
Ninu isa oku won.

4 mf Awa jinde pelu Kristi,


T‘O fun wa l‘ohun gbogbo,
Ojo, iri, ati ogo
T‘o ntan jade l‘oju Re;
Oluwa ba ti wa l‘aye,
Fa okan wa s‘odo Re
cr K‘awon angeli sa wa jo
Ki won ko wa d‘odo Re.

5 ff Aleluya, Aleluya,
Ogo ni fun Olorun;
Aleluya f Olugbala
Enit‘ t‘O segun iku;
Aleluya, f‘Emi Mimo
Orisun ‘fewa mimo;
Aleluya, Aleluya
F‘Olorun Metalokan.
Amin.

336 L.M.
Emi li Eniti O mbe laye ti o si ti ku;
si kiyesi i, Emi si mbe laye titi lae —
Amin. Ifi. 1:18.

1 p J esu, Ore elese ku,


Awon omo Salem nsokun,
Okunkun bo oju orun,
Isele nla se lojiji.

2 p Eyin Mimo, e wa sokun,


Eni t‘O jiya n‘tori yin;
pp On sokun kikoro fun yin,
O ta ‘je Re Owon fun yin.

3 mp Ife at‘edun yi l‘eke;


Oba ogo ku fun eda;
Wo ayo airotele de;
Jesu t‘O ku, si tun jinde!

4 cr Olorun ko ‘boji sile,


‘Boji ko le da ‘jinde ro!
Ogun angel sin LO s‘ile;
Won fayo gba soke orun.

5 f Ma sokun mo, eyin mimo,


E so p‘Olugbala joba,
E korin ti isegun Re
F L‘ori esu ati iku.

6 f E wipe, ―Oba pe titi‖,


IWO ta bi lati gba wa,
E bi ‘ku pe ―Oro re da?‖
―Iboji, isegun re da.‖
Amin.

337 CM
Nigbati Jesu gbo, O da li ohun pe:
Ma beru. Lk. 8:50.

1 mf Eyin ti e nwa Oluwa,


Ma jek‘eru ba yin;
E fayo bojuwo ibi
Ta ti te Jesu si.

2 cr Oluwa lye di oku,


Ise ife l‘eyi;
Idake iku gba l‘aya
To fi gbogbe fun O.

3 f Gb‘oju soke, korin iyin;


Olugbala tun ye;
Gbogbo agbara ‘ku ko to
Da Asegun duro.

4 mf Ga ju gbogbo angeli lo
L‘O gb‘ori Re soke;
Eni t‘O gbe aarin oku,
Joba ayeraye.

5 f Awon mimo yo ji dide


Pel‘a yo bi Tire!;
Won o si b‘Oluwa goke
LO s‘aye ailopin.
Amin.

338 10.11.11.11. & Ref.


Ko ha ye ki Kristi ki o jiya nkan
Wonyi ki o si WO inu ogo Re lo? Lk. 24:26.

1 mf T ire ni ogo, Omo nla Baba


Titi ni ‘segun na t‘O ni lori ‘ku
Awon angeli to y‘okuta na kuro
F‘aso ogbo na lele niboji Re
F Tire ni ogo Omo nla Baba
Titi ni‘segun na t‘O ni lori'ku

2 f Wo! Jesu ji dide ninu oku


O si fi ‘fe tu eru okan wa ka
K‘ijo Olorun f‘ayo korin ‘segun
Oluwa mbe, iku so oro re nu.

3 mf Aigba O gbo bila, Kristi Jesu


Laisi Re ko s‘iye, ran aini wa lowo
Mu wa j‘asegun lo nipa ife Re.
Tit‘ ao koja Jordan sile wa orun.
Amin

339 10.10.10.10. & Ref.


Tali Oba ogo yi? Oluwa awon omo ogun;
On na li Oba Ogo. OD. 24:10.

1 f Ke Kabiyesi! gbe ilekun soke;


Lenu ona re Oba Ogo nduro!
Si okan re, sile ese jade,
Dide jeki Oba Ogo wole.
ff Tali On? Tal‘Oba Ogo yi?
Jesu Oluwa li ola ye fun
Ke Kabiyesi! Wole n‘waju Re
Se l‘Oba, l‘Oba Oba gbogb‘eda.

2 mf Lati agbala orun lojo na,


O Sokale ni ara erupe;
Fun wa n‘ijiya, ibanuje Re,
Ise irora ati ekun Re.

3 mp A kan mo ‘gi ika ati ‘tiju


F‘eje Re ta ta ‘le lo se w‘aye;
Gbo lat‘enu Re igbe irora,
Nitori wa l‘Olugbala se ku.

4 f Iku ko le bori Re niboji,


Lowuro lo jade kuro nibe,
O ji dide, O njoba ni oke,
Ki gbogb‘aye fiyin fun Oluwa.
Amin.

340 K. 170:t.H.C.245 S.M


O jinde nitori idalare wa. Rom. 4:25,

1 f A mu ileri se
Ise 'gbala pari;
Oto at‘anu di ore
Om‘Olorun jinde

2 f Okan mi, yin Jesu,


T‘o ru gbogb‘ese re,
P T‘o ku f‘ese gbogbo aye,
Cr O wa k‘o ma ku mo.

3 mp Iku Re ra ‗simi,
Fun o l‘O jinde
Ff Gbagbo, gba ekun ‗dariji
T‘a sa l‘ami eje
Amin

341 7.7.7.7
O si wi fun awon omo ehin pe,
On ti ri Oluwa. Jn 20:18

1 f Orun, korin! Aye, yo


Anglei at‘eniyan
E yi ka b‘O ti ndide,
E gbe ‗yin Jesu yin ga.

2 f A ti fo ejo l‘ori
A segun ‗ku at‘Esu,
Labe Jesu t‘O goke,
A ti mu ‗gbekun l‘eru

3 f Ise at‘ija Re tan,


O lo sinu ayo Re,
O si mbe f‘awon Tire,
Nibi ite Baba Re.
Amin.

342 C.M
E yara lo so fun awon omo ehin
Re pe, O Jinde. Mat. 28:7.

1 mf Mo wi fun olukuluku
F Pe, On ji, Osi ye;
O si wa larin wa pelu,
Nipa emi iye.

2 E wi fun enikeji yin,


Ki won ji pelu wa,
K‘imole k‘o wa kakiri
Ni gbogbo aye wa.

3 Nisisiyi aye yi ri
Bi ile Baba wa:
Iye titun ti On fun ni,
O so d‘ile Baba.

4 mf Ona okun ti On ti rin


Mu ni lo si orun;
Eni t‘o rin bi On ti rin.
Y‘o d‘odo Re l‘orun.

5 f On ye, O si wa pelu wa,


Ni gbogbo aye yi;
Ati nigbat‘ a f ara wa,
F‘erupe ni ‘reti.
Amin.

343 6.6.6.6.8.8
Awon Oba aye kese jo, ati awon
ijoye ngbimo po si Oluwa. OD. 2:2.

1 ff B‘elese s‘owopo,
Ti won nde s‘Oluwa,
Dimo si Kristi Re,
Lati gan Oba na,
B‘aye sata,
Pelu Esu,
Eke ni won,
Won nse lasan.

2 f Olugbala joba!
Lori oke Sion;
Ase ti Oluwa,
ff Gbe Omo Tire ro:
Lati boji
O ni k‘O nde,
K‘O si goke,
K‘O gba ni la.

3 mf F‘eru sin Oluwa,


Si bowo fase Re;
F‘ayo wa sodo Re,
F‘iwariri duro;
p E kunle fun Un
K‘e teriba;
Sot‘ipa Re,
Ki Omo na!
Amin.

344 8.8.6.D.
Wo ti di igbekun ni igbekun LO
OD. 68:18.

1 mf Jesu t‘Oku, k‘Ogb‘aye la


Jinde kuro ninu oku,
Nipa agbara Re;
ff A da sile lo wo iku,
O d‘igbekun n‘igbekun lo,
cr Oye, k‘O ma kumo.

2 Eyin om‘Olorun, e wo
Olugbala ninu ogo;
O ti segun iku:
Ma banuje, ma beru mo,
O nio pese aye fun yin,
Yio mu yin lo ‗le.

3 mf O foju anu at‘ife


Wo awon ti O ra pada;
Awon ni ayo Re;
O ri ayo at‘ise won,
O bebe ki won le segun,
ff Ki won ba joba lae.
Amin.
345 S.M.
Kristi ti jinde kuro ninu oku I. Kor. 15:20.

1 f ―O luwa ji loto,‖
Ihin na ha s'oto?
p Won ti ri p‘Olugbala ku,
cr Won ri l‘aye pelu.

2 f ―Oluwa ji loto‖
Oto ko fe ju yi;
Anu at‘otito pade,
Ti won ti ns‘ota ri.

3 f ―Oluwa ji loto,‖
Ise Re l‘o setan;
F A da ide onigbowo,
A se apa iku.

4 f ―Oluwa ji loto,‖
mf Boji ko le se mo;
Awon t‘o ku si ji pelu,
Cr Won ki o si ku mo.
Amin.

346 6s. 8s.


Nigbati nwon wo inu iboji, nwon ko
Si ba oku Jesu Oluwa. Lk. 24:3

1 f O luwa ji loto
Olugbala dide,
O f‘agbara Re han;
L‘or‘orun apadi:
N‘iberu nal: awon eso
Subu lule won si daku

2 Wo, egbe Angeli


Pade l‘ajo kikun:
Lati gbo ase Re
Ati lati juba;
Won fayo wa, won si nlo lo,
Lati orun s‘iboji na.

3 Won tun fo lo s‘orun.


Won mu ‗hin ayo lo;
Gbo iro orin won,
Bi won si ti nfo lo
Orin won ni Jesu to ku
Ti ji dide; O ji loni.
4 Eyin t‘a ra pada
Egberin ayo na:
Ran iro re kiri'
Si gbogbo agbaye
E ho fayo Jesu t‘O ku
Ti ji dide: ki y‘o ku mo

5 Kabiyesi! Jesu!
T‘O f‘eje Re gba wa
Ki iyin Re kale
Iwo t‘O ji dide
Aba O ji asi joba,
Pelu Re lai; loke orun.
Amin.

347 8.7.8.7.D.
Emi o si se awon ati ibiti o yi oke
mi ka ni ibukun. Esek. 34:26

1 mf Olorun wa mbe larin wa,


Lati bukun gbogbo wa,
Wo oju orun b‘o ti su
Yo ro ojo ibukun;
F K‘o de Oluwa, a be O
Je k‘ojo Ibukun de;
Awa nduro, awa nduro,
M‘okan gbogbo wa soji

2 mf Olorun wa mbe larinwa


Ninu ile mimo yi,
Sugbon a nfe ‗tura okan wa
At‘opo o‘ofe Re

3 Olorun wa mbe larin wa,


K‘a mu ebe wa t‘O wa,
Ki ife Re ba le gberan
Lati m‘okan wa gbona.

4 Jesu fi ‘bere wa fun wa,


B‘ati fi ‗gbagbo kunle,
di Jo si ferese anu Re
K‘o tu ‘bukun sori wa.
Amin.

348 S.M.
Ojo kan ninu agbala Re san ju
egberun ojo lo OD. 84:10.

1 mf Kabo! Ojo‘simi
T‘ or‘Oluwa jinde;
Ma bo wa s‘okan ti nsoji,
At‘oju ti nyo yi!

2 Oba Tika Re wa
BO eni Re loni,
Nihin l‘a le joko, k‘a ri,
K‘a fe, k‘a yin, k‘a sin.

3 Ojo kan nibiti


‘WO, Oluwa mi ngbe;
O san j‘egberun OJO LO
T‘a nje faji ese

4 f Okan mi yo f ayo
Wa n‘iru ipo yi,
Y‘o joko, y‘o ma korin LO
Tit‘ aye ailopin.
Amin.

349 7.7.7.7.D.
Ago Re wonni ti lewa to?
OD. 84:1.

1 f Bugbe Re ti l‘ewa to
N‘ile ‘mole at‘ife!
‘Bugbe Re ti l‘ewa to
L‘aye ese at‘osi!
Okan mi nfa ni toto
Fun idapo eeyan Re
Fun imole oju Re
Fun ekun Re Olorun.

2 f Ayo ba awon eye


Ti nfo yi pepe Re ka,
Ayo okan t‘o nsimi
L‘aya Baba l‘o poju,
Gege b‘adaba Noa
Ti ko r‘ibi simi le,
Won pada s‘odo Baba

Won si nyo titi aye.


3 f Won ko simi iyin won
Ninu aye osi yi;
Omi sun ni aginju,
Manna nt‘orun wa fun won
Won nlo lat‘ipa de ‘pa
Titi won fi yo si O;
Won si wole l‘ese Re
T‘o mu won la ewu ja.
4 mf Baba, je ki njere be;
cr S‘amona mi l‘aye yi;
F‘ore-ofe pa mi mo;
Fun mi l‘aye l‘odo Re;
IWO l‘orun, at‘asa;
To okan isina mi,
IWO l‘orisun ore,
RO ojo Re s‘ori mi.
Amin.

350 L.M. & Ref.


Gba mi nisisiyi, mo be O Oluwa.
OD. 118:25.

1 f H osana si Oluwa wa
Hosana si Jesu Oba!
Si Eleda Olugbala
K‘aye, k‘orun ko Hosana,
KO Hosana, ―Hosana loke orun‘

2 f Hosana l‘orin angeli


Hosana l‘orin ti a gbe
L‘oke, nisale, yi wa ka,
Oku at‘aye ngbe ‘rin na
ff Ko Hosana, ―Hosana l‘oke orun‖

3 mf Olugbala ti ntoju wa
Pada wa ‗le adura yi,
A pejo ni oruko Re,
Mu ileri Re se si wa
cr Ke Hosana, ―Hosana loke orun‖

4 f Sugbon bori ohun gbogbo


Fi Emi Re kun okan wa:
Ki okan wa je ibugbe
Mimo ati yiye fun O;
cr Ko Hosana, ―Hosana loke orun‖.

5 p L‘ojo ‘kehin ojo eru


T‘aye on orun o koja;
cr Awon ti a ti rapada,
Yo tun gbe orin iyin na;
ff KO Hosana, ―Hosana l‘oke orun‖.
Amin.

351 L.M.
Mo mo pe Oludande mi mbe
Jobu 19:25.

1 f M o mo p‘Oludande mi mbe
Itunu nla l‘eyi fun mi!
p O mbe, Eni t‘O ku lekan;
f O mbe, ori iye mi lae.

2 f O mbe lati ma bukun mi,


p O si mbebe fun mi loke,
ff O mbe lati ji mi n‘boji,
Lati gba mi la titi lae.

3 cr O mbe, Ore kori-kosun


Ti y‘o pa mi mo de opin,
F O mbe, emi o ma korin .
Woli, Alufa, Oba mi.

4 O mbe lati pese aye


Y‘O si mu mi de be l‘ayo;
O mbe, ogo foruko Re;
Jesu Okan na titi lae.

5 f O mbe, ogo foruko Re,


Olugbala kanna titi,
A! ayo l‘oro yi fun mi:
F ―Mo mo p‘Oludande mi mbe‖
Amin.

352 C.M.
Oluwa, mu ise Re soji.
Hab.3:2.

1 mf J esu Olugbala aye,


A ntoro ‘bukun Re,
si ‘lekun aitase sile
fun ‘wasu oroRe.

2 mf Ko awon to nu bo sile,
Gba won lowo esu;
cr Jeki won ri itewogba,
Ki won mo ‘gba anu.

3 mf Olufe okan: Iwo mo


Riri ohun t‘O ra;
Wa f‘ara han awon Tire
Pelu gbogb‘ ogbe Re,

4 Mu ki okan won lile ro,


Iwo t‘O ku f‘eda;
Fi eri if?e Re han won;
Ese, owo, iha.

5 p Ese Re la kan mo igi,


k‘Otese won mole;
A na apa Re lati gba
Awon ti won pa O.

6 Iha Re ni‘bi orisun,


Nibi gbogbo eda
cr Le lo mu n‘nu omi iye,
Ki won we ‘ra won mo.

7 mf ‘Wo nfe f‘eje Re jeri pe


Otito l‘oro na;
Ogbe Re nke s‘elese pe:
p Mo jiya yi fun o.
Amin.

353 C.M.
E gbe ori nyin soke enyin enu ona
ki Oba Ogo WO inu ile wa. OD 24:7

1 f Agbe ilekun wura ro,


A si si won paya;
Oba Ogo si ti wole
Lo s‘odo Baba Re

2 mf Oluwa‘Wo ti saju lo
Pese aye fun wa,
Ki a ba le wa lodo Re,
Lati w‘oj‘ Olorun

3 Imole t‘o logo ntan lae


Li ona aye wa;
Imole to tan s‘okunkun
Di Ti ko je ka ri O.

4 mf Jowo gbe okan wa soke,


F‘ore-ofe fun wa
Ba ti nrin kiri l‘aye yi
Ka ni ‘sura lorun.

5 f Ki ireti at‘ife wa
Le ma wal‘odo Re;
Ma gbe ‘nu wa, ki a le wa
Ninu Re titi lae.
Amin.

354 6.6.6,6.8.8.
Jesu na yi, ti a gba soke orun yio pada
be, bi e ti rii ti o nlo si orun.
Ise. A . 1:11.
1 mf Eyin t‘e fOluwa,
To mo ‘pa Re, e wa,
E dapo n‘isokan,
Lati yin ore Re,
F‘orun at‘aye, e kede
Oruko Oludande yin.

2 O rite Re l‘oke
At‘ogo Re sile;
O fife sokale,
O sokun, O si ku;
Iya to je tani le wi
Lati gb‘okan wa lowo iku?

3 Lati‘boji; O nde
N‘isegun lor‘iku;
O k‘awon ota Re,
To segun lat‘ibe;
O si l‘awon orun koja
N‘isegun s‘ite Olorun.

4 O fere pada wa,


Keke Re ki yo pe,
Lati m‘omo Re LO
Si ile ailopin;
Nibe l‘ao ri lojukoju,
L‘ao ko isegun ore Re.

5 Jesu, a ko le san
Gbese ‘fe Re ta je,
KO wa ba ti le san;
Gba ‘yin at‘ope wa,
T‘okan t‘ara wa la fun O;
Bo tile kere, te ‘WO gba.
Amin

355 8.7.8.7. D.
OWO otun Re, ati apa Re mimo,
Li o ti mu igbala wa fun ara Re.
OD. 98:1.

1 f Wo Asegun b‘O ti g‘oke,


Wo Oba n‘nu ola Re;
Ogun keke ofurufu
LO s‘orun agbala Re;
Gbo orin awon angeli
Aleiuya ni nwon nko,
Awon ‘lekun si si sile,
Lati gba Oba orun.
2 mf Tani ologo ti mbo yi,
T‘On ti ipe Jubeli
p Oluwa awon ‘mo-ogun,
On t‘O ti segun fun wa
p O jiya lor‘agbelebu
O jinde ninu oku,
F O segun esu at‘ese
Ati gbogbo ota Re.

3 mf Bo ti nbuk‘awon ore Re,


A gba kuro lowo won.
Bi oju won si ti nwo LO,
O nu nin‘awo sanma;
Eni t‘O ba Olorun rin
To si nwasu otito,
On, Enok‘ wa li a gbe LO
S‘ile Re loke Orun.

4 mp On Aaron wa gbe eje Re


WO inu ikele lo;
Joshua wa ti wo Kenan‘
Awon Oba nwariri;
mf A fi di eya Israel‘
Mule nibi ‘simi won,
Elija wa si fe fun wa
N‘ilopo meji Emi.

5 f Iwo ti gbe ara wa WO


Lo s‘ow‘Otun Olorun;
A si joko nibi giga
Pelu Re ninu ogo;
ff Awon angeli mbo Jesu
Eniyan joko lor‘ite;
Oluwa, b‘Iwo ti goke
Jo je ka le goke be.
Amin

356 1.1.1.1. & Aleluya


Nigbati Oluwa si ti ba won soro tan,
a si gba A lo soke orun. Mk. 16:19.

1 f Alafia f Ojo na - Aleluya


T‘O pada s‘ite lorun - Aleluya
p Krist‘ t‘a ti fifun eda - Aleluya
f Tun pada soke orun - Aleluya
2 ff Iyin duro de nibe - Aleluya
Gb‘ori s‘oke, ilekun - Aleluya
Si ogo orun paya - Aleluya
Je k‘Oba ogo wole - Aleluya
3 f Orun, gba Oluwa re - Aleluya
mp Sibe On feran aye - Aleluya
f Bo ti pada s‘ite Re - Aleluya
mp Sibe O pe wa n‘Tire - Aleluya

4 mp Wo! O gbowo Re soke - Aleluya


Wo! O fapa ife han - Aleluya
Gbo, bi O ti nsure fun - Aleluya
Ijo Re l‘aye nihin - Aleluya

5 mf Sibe O mbebe fun wa - Aleluya


Ebe Re yo si bori - Aleluya
cr O npese aye fun wa - Aleluya
f On l‘akobi iran wa - Aleluya

6 cr Oluwa lae lao ma ke - Aleluya


S‘Iwo ti a gba soke - Aleluya
Pe, wo awa ‘ranse Re - Aleluya
Ba ti te ‘ju wa mo O - Aleluya

7 Bo ti je pe agba O - Aleluya
Soke kuro lodo wa - Aleluya
Jo, je k‘okan wa dide - Aleluya
Ba O lo soke orun - Aleluya
8 Nibe lao wa pelu Re - Aleluya
N‘ijoba ayeraye - Aleluya
Nibe l‘ao ri oju Re - Aleluya
Li orun awon orun - Aleluya
Amin

357 7.6.7.6.D.
IWO ti goke si ibi giga. OD. 68:18.

1 f Kristi, l‘ehin isegun


IWO ti goke lo;
Kerub‘ at‘ogun orun
Wa sin O goke lo;
mf K‘aye so ‘tan na jade,
cr Imanueli wa,
f Ti s‘ara iy‘ara wa,
Gori ite Baba.

2 mf ‘Lekun orun si sile,


IWO ha le gbagbe
Awon to fe 0, Jesu
Ti iwo lat‘Olifi?
L‘okan aya Re la ko
Oruko gbogbo si;
Alufa l‘aye, l‘orun,
Okan nal‘ailopin.
3 mf Nibe lo duro, to nso di
Agbara eje Re;
O mbebe fun elese,
‘Wo alagbawi wa,
p Gbogbo ayida aye
T‘ayo, t‘aniyan wa
cr N‘iwo nse iyonu si,
T‘iwo si mbebe fun.

4 p Nitori itoye nla


Ti agbelebu Re,
K‘O fi Emi Mimo Re
So ofo wa d‘ere,
Nipa igbiyanju wa
Okan wa o goke;
Lati ba O gbe titi,
Li,ayo ailopin.
Amin.

358 6.6.6.6.8.8.
E ho iho ayo si Oluwa,
Enyin ile gbogbo. OD. 100:1.

1 f Olorun goke lo
Pelu ariwo nla,
Awon ipe orun
Nf‘ayo angeli han;
ff Gbogbo aye yo, ke gberin
E f‘ogo fun Oba Ogo.

2 mp O j‘eniyan laye,
F Oba wa ni loke;
Ki gbogbo ile mo
Ife nla Jesu wa.

3 f Baba fi agbara
Fun, Jesu Oluwa;
Ogun angel‘ mbo O;
On l‘Oba nla orun.

4 f L‘or‘ite Re mimo,
O gb‘opa ododo;
Gbogbo ota Re ni
Yio ku LO bere.

5 f Ota Re l‘ota wa;


Esu, aye,ese;
Sugbon yo rehin won,
Ijoba Re yo de.
6 f Titi gbogbo aye
Ta fododo tun bi
Yo ba ogun orun
Gbe orin ayo nla.
Amin.

359 D.S.M.
Eniti o ti Sokale li o si ti
rekoja gbogbo awon Orun. Efe. 4:10.

1 f Iwo ti goke lo
S‘ile ayo orun
Lojojumo y‘ite Re ka
L‘a ngbo orin iyin;
P Sugbon awa nduro
Labe eru ese
Cr Jo ran Olutunu Re wa,
Ko si mu wa lo ‗le

2 f Iwo ti goke lo;


P Sugbon saju eyi,
O koja ‗rora kikoro
Cr Ko to le de ade;
Mp Larin ibanuje
L‘ao ma te siwaju
Cr K‘ona wa to kun f‘omije
To wa si odo Re

3 f Iwo ti goke lo
Iwo o tun pada;
Awon egbe mimo loke
Ni yo ba O pada
Mf Nipa agbara Re,
K‘a wa, k‘a ku n‘nu Re,
Cr ‗Gbat‘ a ba ji lojo ‗dajo,
F Fi wa si otun Re.
Amin

360 7.7.7.7.D.
A gbe E soke; awosanmo si gba
A kuro li oju won. Ife A. 1:9.

1 p O ti lo, awosanmo
Ti gba kuro loju wa
F Soke orun, nibiti
Oju wa ko le tele;
O ti kuro l‘aye yi,
O ti de ibi mimo,
Lala ati ‘rora tan,
Ija tan, O si segun.

2 p O ti lo, awa si wa
L‘aye ese at‘ iku,
A ni ‘se lati se fun,
L‘aye to ti fi sile
cr Ka si tele ona Re;
Ka tele tokan tokan,
Ka s‘ota Re di ore,
Ka fi Krist‘ han n‘iwa wa.

3 p O ti lo, On ti wipe,
―Odara ki Emi lo‖
Ni ara sa lo ya wa,
Sugbon or‘ofe Re wa,
mf On ni awa ko ri mo
A ni olutunu Re;
F Emi Re si jo ti wa,
O ns‘agbara wa d‘otun.

4 p O ti lo, l‘ona kanna


Lo ye k‘Ijo Re ma LO
Ka gbagbe ohun ehin
F Kasi mate siwaju,
Oro Re ni ‘mole wa
Titi de opin aye
Nibiti oto Re wa
Yo pese fun aini wa.

5 p O ti lo l‘ekan si i
A o tun foju wa ri;
O wa bakanna lorun
Gege b‘o ti wa l‘aye;
N‘nu ‘bugbe to wa nibe
Yo pese aye fun wa;
p Ninu aye ti mbo wa
A o j‘okan pelu Re,

6 p O ti lo fun ire wa,


E jeki a duro de,
F O jinde ko si nihin,
Oti goke re orun,
Je ka gb‘okan wa soke
Sibiti Jesu ti lo,
Si odo Olorun wa.
ff Nibe l‘alafia wa.
Amin.

361 10.10.10.10.
Emi nlo, lati pese aye sile fun yin.
Jn. 14:2.

1 f E gbo iro orin ayo orun,


Orin ayo ti isegun Jesu;
Gbogbo ota l‘o teri won ba fun,
p Ese, iku, isa-oku pelu.

2 f O se tan lati lo gba ijoba,


Fun Baba, Olorun ohun gbogbo;
O se tan lati lo gba iyin nla,
T‘o ye Olori-ogun ‘gbala wa.

3 p Ohun ikanu ni lilo Re, fun


Awon ayanfe Omo-eyin Re
F E ma se konnu l‘oro itunu.
―Emi nlo pese aye yin sile''

4 Orun gba LO kuro leyin eyin,


Awosanma se Olugbala mo;
ff Awon Ogun-orun ho fun ayo,
Fun bibo Kristi Oluwa ogo.

5 mp E mase ba inu yin je rara


Jesu, ireti wa, yio tun wa,
f Yoo wa mu awon eeyan Re lo
Sibiti won o ba gbe titi lae.
Amin.

362 6.6.6.6.8.8.
A wa ni olori Alufa nla kan ti o ti koja LO
sinu awon orun. Heb. 4:14.

1 f Onigbagbo, e wa,
Israeli t‘emi:
K‘a fi ayo pejo,
K‘ agboyin didun yi;
ff Jesu goke, O lo s‘orun,
‗Alufa giga wa r‘orun.

2 mf Ojo etutu de,


Israeli, e pe;
P A ti ru ebo tan,
Ebo Odagutan;

3 Ibi mimo julo,


L‘Olugbala wa lo,
mp Pelu eje mimo
T‘O ju t‘ewure lo;

4 ff Kristian, e ho fayo,
Olorun gb‘ ebo wa;
F Jesu mbebe pupo,
Bi Alagbawi wa;
ff Enikeni t‘o fori fun,
Y‘o ni iye ainipekun.
Amin.

363 C.M.
Bi o ti nsure fun nwon, a ya a
kuro LODO nwon a si gbe e LO si Qrun.
Lk. 24:51.

1 A ha iho ayo mimo


S‘Olorun Oba nla
K‘ile gbogbo lo ahon won
K‘o si ko ‘rin ‘'segun.

2 Jesu Oluwa wa goke


Eso orun yika,
Won ba goke bi O ti nlo
Pelu iro fere.

3 B‘Angeli ti nyin Oba won


K‘eda ko orin na:
Ki aye korin ola Re:
O joba gbogb‘ aye

4 F‘iberu nla wa iyin Re


Fi oye korin na,
Ma fi ahon etan fun u
Nipa iyin eto.
Amin.

364 11.11.11.11.
E mase pa ina Emi. I Tes. 5:19.

1 mf IWO elese, Emi nfi anu pe


Okan re to ti yigbi ninu ese;
Mase ba Emi ja, ma pe titi mo,
Ebe Olorun re le pari loni.

2 f Omo Ijoba, ma s‘eru ese mo,


Gb‘ebun Emi Mimo ati itunu,
Ma bi Emi ninu, Oluko re ni;
Ka ba le se Olugbala re l‘ogo.

3 p Tempili d‘ibaje, ewa re d‘ile,


Ina pepe Olorun fere ku tan;
Bi a fi ife da, o si le tun ran,
Mase pa ‘na Emi, Oluwa mbo wa.
Amin.

365 9.4.9.4. & Ref.


Emi mi siyo si Olorun
Olugbala mi. Lk. 1:47.

1 mf Okan mi sipaya, Oluwa,


Wole, Wole,
Igbagbo mi ro mo oro Re
Wole, Wole.
F Ma ba mi gbe titi Oluwa,
Ohun ti O fe ni un o fe
Fi okan mi se ‘bugbe Re laelae
Wole, Wole.

2 mf Beni aye mbe fun Oluwa


Wole, Wole,
Dide Re mu mi sun mo O si
Wole, Wole.

3 mp Mo da O duro s‘ode pe ju
Wole, Wole,
Dari eyi ji mi Oluwa
Wole, Wole.

4 p Mo gbo, O nkan‘lekun, Oluwa


Wole, Wole
Nko ni da O duro s‘ode mo
Wole, Wole.
Amin.

366 8.7.8.7. & Ref.


Sugbon enyin o gba agbara,
nigbati Emi Mimo ba ba le nyin.
Ise. A. 1:8.

1 mf ‘Gbat‘ agbara Olorun de,


Li ojo Pentikosti,
Sa if oju s‘ona pari,
‘Tori won ri Emi gba.
ff Ran agbara, Oluwa,
Ran agbara, Oluwa,
Ran agbara, Oluwa,
Ki O si baptis‘ wa.

2 f Ela ‘han ina ba le won


Won si wasu oro na,
OPOLOPO eeyan gbagbo
Won yipada s‘Olorun.
3 cr A nw‘ona fun Emi Mimo
Gbogbo wa f ohun sokan
Mu ‘leri na se, Oluwa,
Ti ase nin‘oro Re

4 f Jo, fi agbara Re kun wa,


Fun wa ni ‘bukun ta nfe;
Fi ogo Re kun okan wa,
Ba ti nfi ‘gbagbo bebe
Amin

36 7 L.M
Emi o tu ninu Emi mi jade
sara eniyan gbogbo. Ise. A. 2:17.

1 mf Oluwa, awa gbagbo pe


Tiwa ni ‘leri igbani;
A nret‘ agbara Pentikost,
Emi Mimo lat‘oke wa.

2 Fun gbogb‘eni ti Kristi pe


Ni ‘leri to daju mbe fun;
O npe gbogbo eyin Tire
E gba oro ti Jesu SO

3 mp Maje kas‘ofo pe titi


N‘ifojusona bibo Re.
cr Ran Olutunu sokale,
K‘alejo orun ba wa gbe.

4 mf A f okan kan pejo nihin,


A nret‘ ileri or‘-ofe
T‘iku Oluwa wa ti ra,
Emi Mimo wa kun ihin.

5 B‘eni bere ba le ri gba


Bo ba mba l‘elese sibe,
Wa b‘iro efufu lile;
Fun gbogbo wa l‘or‘ofe Re

6 Sa wo, Iwo l‘okan wa nwa,


A si npongbe isokan Re;
cr Da ina iye sinu wa,
Fi okan wa se ‘bugbe Re.
Amin.

368 C.M.
Emi o tu Emi mi jade
sara eniyan gbogbo. Joe. 2:28.
1 mf Emi Mimo, mi s‘okan wa,
Ka mo agbara Re;
cr Orisun Emi ‘so tele,
T‘imole at‘ife

2 mf Emi Mimo l‘agbara Re


L‘awon Woli sise;
Iwo lo,nfi oto han wa,
Ninu iwe mimo

3 mf Adaba orun, na ‗ye Re


Bo okun eda wa:
Jeki ‘mole Re tan sori,
di Emi aisoto wa

4 mf A o mo. Olorun daju


B‘Iwo ba mbe n‘nu wa
Ao mo ‗jinle ife mimo
Pelu awon Tire.
Amin

369 8.6.8.4.
Emi o si bere lowo Baba On o si fun nyin
li Olutunu miran ki o le ba nyin gbe titi.
Jn. 14:16,

1 mp Olurapada wa, k‘On to


Dagbere ikehin,
O fi Olutunu fun ni,
Ti mba wa gbe.

2 p O wa ni awo adaba,
O na iye bo wa;
Otan ‘fe on alafia
S‘ori aye.

3 mf O de, O mu ‘wa rere wa,


Alejo Olore;
‘Gbat‘ O ba r‘okan irele
Lati magbe.

4 p Tire l‘ohun jeje tangbo,


Ohun kelekele;
Ti mbani wi, ti nl‘eru lo
Ti nso t‘orun.

5 Gbogbo iwa rere ta nhu


Gbogbo isegun wa;
Gbogbo ero iwa mimo
Tire ni won.
6 mf Emi Mimo Olutunu,
Fi ‘yonu be wa wo,
cr Jo s‘okan wa ni ‘bugbe
Re Koye fun O.
Amin.

370 C.M.
Emi Olorun si nrababa loju omi. Gen. 1:2.

1 f ‘G banit‘ Olorun sokale,


O wa ni ibinu,
Ara si nsan niwaju Re,
Okunkun oun ina.

2 p Nigbat‘O wa nigba keji,


O wa ninu ife;
pp Emi Re si ntu ni lara
B‘afefe owuro

3 f Ina Sinai ijo kini,


T‘OWO re mbu s‘oke,
mp Sokale jeje bi ade,
Si ori gbogbo won.

4 f Bi ohun eru na ti dun


L‘eti Israeli,
B‘iro ipe, ti angeli
Wariri lati gbo

5 mf Be gege nigbat‘ Emi wa


Bale awon Tire,
cr Iro kan si ti orun wa;
Iro iji lile.

6 f O nkun ijo Jesu, o nkun


Aye ese yi ka,
mp L‘okan alaigboran nikan
Ni aye ko si fun.

7 mf Wa, ogbon, Ife at‘ Ipa;


Fun wa leti igbo;
p Ka ma so akoko wa nu;
Ki ‘fe Re le gba wa.
Amin

371 D.S.M.
Nwon si kun fun Emi Mimo Ise. A. 2:4.

1 mf ‘W 0 Olorun Emi
L‘ojo ‘tewogba yi
Gegebi ojo Pentikost‘
Sokale l‘agbara,
L‘okan kan la pade
Ninu ile Re yi;
A duro de ileri Re,
p Emi ore ofe.

2 p B‘iro iji lile


Wa kun nu ile yi;
cr Mi Emi isokan si wa:
Okan kan, imo kan;
Fun ewe at‘agba
L‘ogbon at‘oke wa;
Fi okan gbigbona fun wa
Ka yin. ka gbadura.

3 mp Emi imole, wa
Le okunkun jade,
Siwaju ni ki ‘mole tan
Titi d‘osan gangan,
Emi otito, wa samona wa titi;
Emi isodomo, si wa
S‘okan wa di mimo.
Amin.

372 8.8.8.D,
Emi Olorun si nra baba loju omi. Gen. 1:2.

1 mf Emi Eleda, nipa Re


La f‘ipile aye sole;
p Ma sai be gbogbo okan wo,
Fi ayo Re si okan wa,
YO wa nin‘ese at‘egbe,
Ko fi wa se ibugbe Re.

2 f Orisun imole ni O,
Ti Baba ti se ileri
IWO ina mimo orun
F‘ife orun kun okan wa;
p Jo tu ororo mimo Re
S‘ori wa bi a ti nkorin.

3 mp Da opo ore-ofe Re
Lat‘ orun s‘ori gbogbo wa;
cr Je ka gba otito Re gbo,
Ka si ma saro l‘okan wa;
F‘ara Re han wa ka le ri
Baba at‘Omo ninu Re.
4 f Ka fi ola ati iyin
Fun Baba, Olodumare,
Ka yin oko Jesu logo;
Eni t‘O ku, lati gba wa;
Iyin bakanna ni fun O
Parakliti ayeraye.
Amin.

373 C.M.
IWO SO mi di aye gege bi oro Re
OD 119:25.

1 mf Emi mimo ‘Daba orun,


Cr Wa li agbara Re;
Ko da inn ife mimo
So okan tutu wa.

2 cr Wo ba ti nra pala nihin


Tafe ohun asan;
Okan wa ko le fo ko LO
Ko de b‘ayo titi.

3 Oluwa ao ha wa titi
p Ni kiku osi yi?
Ife wa tutu be si O,
Tire tobi si wa.

4 f Emi mimo ‘Daba orun


cr Wa ni agbara Re;
Wa da ‘na ‘fe, Olugbala
Tiwa o si gbina.
Amin.

374 7.7.7.
Emi o si fi Emi titun sinu yin. Esek. 11:19.

1 mp Wa, Parakliti mimo,


Lat‘ ibugbe Re orun;
cr Ran itansan ‘mole wa

2 mf Baba talaka, wa ‘hin,


Olufunni l‘ebun, wa,
Imole okan, jo wa.

3 p Baba Olutunu, wa
Alejo toto f‘okan,
Pelu itura Re, wa.

4 mf ‘Wo n‘isimi n‘nu lala


Iboji ninu oru,
Itunu ninu‘ponju.

5 p ‘Wo‘ mole to gara


cr Tan sinu aye awon
Eniyan Re Oloto.

6 Laisi Re, kil‘eda je?


Ife at‘ero mimo
Lat‘ odo Re wa ni won

7 p Eleri, so di mimo
Agbogbe, masai wo san,
Alaiseso mu s‘eso

8 Mu okan tutu igboan,


M‘agagidi, teriba,
Pe asako wa jeje

9 cr F‘emi ‗jinle Re meje


Kun awon oloto Re,
F‘agbara Re s‘abo won.

10 f Ran or‘ofe Re, sihin,


Ekun igbala l‘aye
At‘alafia l‘orun
Amin

375 8.8.8.D.
Nitori eso Emi wa ni ti ohun rere
gbogbo, ati ododo, ati otito. Efe. 5:9.

1 mf Wa, mi si wa, Emi Mimo,


Tan ‘ na orun si okan wa;
Emi a fororo yan ni
Ti f‘ebun meje Re fun ni;
Ise nla Re at‘oke wa
N‘itunu, iye, ina, ife.

2 F‘imole Re igba gbogbo


Le okunkun okan wa lo.
mf F‘ororo ore-ofe Re
Pa oju eri wa, ko dan;
di L‘ota jina si ‘bugbe wa:
p Ire n‘igbe‘ biti‘ Wo nso

3 mf Ko wa, ka mo Baba, Omo,


Pelu Re li okansoso
cr Titi aye ainipekun,
Ni k‘eyi ma je orin wa;
F Lae, iyin, eye ni fun O .
Baba, Omo, Emi Mimo.
Amin.

376 L.M.
lye awon ti a fi Emi Mimo Olorun to,
awon ni ise omo Olorun.
Rom. 8:14.

1 mf Emi Mimo‘Daba orun,


Wa mu itunu sokale;
F Se oga at‘Oluto wa,
Ma pelu gbogbo ero wa.

2 mf Jo fi otito Re han wa,


Ka le fe, ka si m‘ona Re,
p Gbin ife toto s‘okan wa,
Ka ma le pada lehin Re.

3 cr Mu wa ka to ona mimo;
Ta le gba d‘odo Olorun:
Mu wa to Krist‘ ona iye,
Maje ki awa sina lo.

4 f Mu wa t‘Olorun ‘simi wa,


Ka le ma ba gbe titi lae;
To wa s‘orun, ka le n‘ipin
L‘OWO Otun Olorun wa.
Amin.

377 C.M.
Nitori eso Emi wa ni ti ohun rere gbogbo,
ati ododo ati otito. Efe. 5:9.

1 mf Emi orun, gb‘adura wa,


Wa gbe ‘nu ile yi;
Sokale pel‘agbara Re,
F Wa, Emi Mimo, wa.

2 mf Wa bi ‘mole si fihan wa
B‘aini wa ti po to;
Wa to wa si ona iye
Ti olododo nrin.

3 Wa, bi ina ebo mimo,


S‘okan wa di mimo,
Je ki okan wa je ore
F‘oruko Oluwa.

4 p Wa, bi iri, si wa bukun


Akoko mimo yi,
Cr Ki okan alaileso wa
Le yo l‘agbara Re.

5 f Wa, bi adaba, n‘apa Re,


Apa ife mimo,
Wa, je ki Ijo Re l‘aye
Dabi Ijo t‘orun.

6 f Emi orun, gb‘adura wa.


S‘aye yi d‘ile Re;
Sokale pel‘agbara Re,
Wa, Emi Mimo wa.
Amin,

378 7.7.7.6.
Emi o dabi iri si Israeli. Hos. 14 : 5

1 mf Emi ‘bukun ti a nsin


Pelu Baba at‘oro,
Olorun ayeraye;
p Gbo wa, Emi mimo.

2 cr Iwo Adaba orun


Iri ti nse lat‘ oke;
Emi ‘ye at‘ina ‘fe,
p Gbo wa, Emi mimo.

3 mf Isun, ipa at‘imo,


Ogbon at‘iwa-mimo,
Oye, imoran, eru;
p Gbo wa, Femi mimo

4 mf Isun ife alafia,


Suru ‘bisi igbagbo,
‘Reti ayo ti ki tan,
p Gbo wa, Emi mimo

5 cr Emi afona han ni,


Emi ti nmu ‘mole wa,
Emi agbara gbogbo
p Gbo wa, Emi mimo.

6 mp ‘Wo t‘O mu Wundia bi,


Eni t‘orun, t‘aye mbo,
Ta ran lati tun wa bi,
p Gbo wa, Emi Mimo.

7 cr 'WO ti Jesu t‘oke ran


Wa tu eniyan Re ninu,
Ki nwon ma ba nikan wa,
p Gbo wa, Emi mimo.

8 ‘Wo t‘On fore kun Ijo,


T‘O nfi ife Baba han,
T‘O nmu ko ma ri Jesu,
p Gbo wa, Emi mimo.

9 mf IWO ti n f‘onje iye


At‘otito na bo wa
Ani, On to ku fun wa
p Gbo wa, Emi mimo

10 mf F‘ebun meje Re fun ni,


Ogbon lati m‘Olorun,
Ipa lati ko ota,
p Gbo wa, Emi mimo

11 mf Pa ese run l‘okan wa,


TO ife wa si ona,
Ba ba nse O mu suru;
p Gbo wa, Emi mimo.

12 cr Gbe wa dide, ba subu,


Ati nigba idanwo,
Sa pe wa pada pele
p Gbo wa, Emi mimo

13 mf Wa k‘O mu ailera le,


F‘igboya fun alare,
KO wa l‘oro ta o so;
p Gbo wa, Emi mimo.

14 mf Wa ran Okan wa lowo,


Lati mo otito Re,
Ki ‘fe wa le ma gbona,
p Gbo wa, Emi mimo.

15 mf Pa wa mo l‘ona toro,
Ba wa wi ‘gba ba nsako
Ba wa bebe l‘adura,
p Gbo wa, Emi mimo

16 mf Emi Mimo, Olufe,


Wa gbe inu Okan wa;
Ma fi wa sile titi,
p Gbo wa, Emi mimo.
Amin.

379 S.M.
Sugbon enyin o gba agbara nigbati
Emi Mimo ba ba le yin. Ife A. 1:8

1 mf Emi alagbara,
Wa joko ninu mi,
Ki O si fun wa n‘idande
Low‘eru on ese

2 cr Emi im‘arale,
Gbe arun ese lo,
Emi iwa mimo pipe
Emi ife pipe

3 M‘ojo na yara de
Ti ao run ese mi,
Ti ohun atijo yo koja,
T‘ohun gbogbo d‘otun

4 di Ese abinibi,
Pare li okan mi;
cr Wole, ki O si le jade,
Gba gbogb‘okan mi kan.

5 mf Oluwa, mo fe ni,
Eri pe, mo nse ‘re
Gegebi ‘fe at‘oro Re
Bo ti to l‘oju Re.

6 di ‘Ko fe ipo giga;


Sa fi eyi ke mi,
Ni ‘gbakugba to ba si ya,
p Gbami s‘orun rere.
Amin.

380 8.6.8.8.6. & Ref.


Enyin ha gba Emi Mimo na nigbati
enyin gbagbo? Ise A. 19:2.

1 mp Emi ki y‘o fi yin sile‖


Laini Olutunu,
Emi yo ran Olutunu
Ti yo ma bayin gbe titi,
Losan ati l‘oru.
mf Emi na ti de sodo re bi?
Olutunu na ha ti de?
Yo fi oye ese ye,aye
‘Gbati Olutunu ba de.

2 Ijo Kristi e dide gba


Ekun agbara yi,
Titi ao mu gbogb‘ asako
Wa sabe ore-ofe Re.
Nipa gbigba Jesu.

3 mf Orun kun fun Pentikosii


Fun gbogbo eniyan,
Je ka fi irele bere
Ileri wa ninu Kristi,
Agbara lat‘orun

4 p Ka tun pada si Pentikost‘


Si iyara oke,
Ka gbadura s‘Oluwa wa,
K‘O ran Emi Mimo si wa,
Ka fi suru duro.
Amin

381 8.8.8.8.8.8.
Ki ise ami ati ise iyanu ki o ma se
li Oruko Jesu Ise A. 4:30.

1 mf Awa pejo s‘iwaju Re


Lati kede ‘gbala kikun;
Lati jewo ore ta gba
Nipa Oruko nla Jesu;
Tewo gb‘ope wa, Oluwa
Te ongbe okan wa lorun.

2 mp Awa mbe O, lakoko yi


F‘agbara Pentikpsti han;
‘Gbati awon ti ongbe ngbe
Ri ‘dariji on ‘wenumo,
La oju awon afoju,
Si eti awon to di ‘ti.

3 p Awon ti eru ese npa


Mbe nihin lati gba ‘wosan;
Gbogbo awon ta npon loju
Lo wa fun idasile won
Soro ‘wosan ki gbogbo won
Le gba iwenumo okan.

4 f F‘igboya fawon ‘ranse Re


Ki won wasu tokan tokan;
Na owo Re lati wosan
K‘ise ‗yanu se l‘oko Re,
Ka ri agbara Re loni
Ka le gbe oruko Re ga.

5 cr Awa nduro bi O ti wi
Je ko ri fun wa b‘oro Re,
K‘aigbagbo tab‘ igberaga
Mase dena agbara Re,
Joba ninu okan gbogbo,
Awa mbe O. Emi Mimo
Amin.

382 8.7.8.7.D. & Ref


Emi o da omi lu eniti ongbe ngbe Isa. 44:3.

1 mf Awa pejo l‘oruko Re


Ninu ile mimo yi.
Ibukun Baba wa la n fe,
A mbere or‘ofe Re;
Lat‘ inu ekun ‘bukun Re
Tio jin ju okun lo,
RO ojo na si wa lori
Ko fi so wa d‘omnira.
F Si ferese orun sile
Ro ojo na s‘ori wa;
Ro ojo igbala kikun,
We gbogbo abawon nu.

2 f Si ferese orun sile,


RO ojo na sori wa,
Yo wa kuro n‘nu iparun,
Gbe wa soke to ga ju;
Ki opo awon elese
Le wa to ife Re wo;
Ka gba won sinu ‘joba Re
Nipa ‘wenu atunbi.

3 f Awa gbagbo pe O mbowa,


Ojo ‘bukun na nbowa;
Iwo eniti ngbadura,
Na apa agbara Re,
Ojo agbara lat‘oke
Ojo ife Kalfari;
Mu ago wa kunwo sile,
Ro ojo nla lat‘oke.
Amin

383 S.M.
O mi si won Jn. 20:22.

1 cr M i si mi, Olorun,
F‘emi titun fun mi,
Ki nle fe ohun ti O fe,
Ki ns‘eyi t‘O fe se.
2 Mi si mi, Olorun,
S‘okan mi di mimo,
K‘ife mi on Tire j‘okan
L‘ero ati n‘ise.

3 Mi si mi, Olorun,
Titi un o di Tire,
Ti ara erupe mi yi
Yo tan ‘mole orun.

4 mp Mi si mi, Olorun,
Emi ki yo ku lae,
Un o ba O gbe n‘iwa pipe
Titi ayeraye.
Amin.

384 11.10.11.10.
Nitoripe Olorun wa, ina ti ijonirun ni.
Heb. 12:29.

1 mf Ina Emi orun, ma jo ninu mi,


Da 'na iwa mimo si okan mi
Orisun ‘mole at‘ibukun gbogbo,
So aye mi di t‘imole titi.

2 cr Ina Emi Orun, je k‘ogo Re tan,


S‘okan mi di mimo fun ogo Re;
Wa da ‘na ife orun si okan mi
Ife ti njere okan f‘Oluwa.

3 Ina Emi orun, ba le mi loni,


Ela ahon bi t‘ina ba le mi,
Mu eyin-ina lati pepe orun;
Fi kan mi l‘enu ki njise fun O,

4 f Ina Emi Orun, ni igba meje


We mi, tun mi we, ki nle r‘oju Re;
Titi aworan Re yo han lara mi
Ki nle ri iran Kristi ju be LO

5 ff Ina Emi Orun f‘ife Re kun mi,


Ki gbogbo aye mi le di Tire;
Emi, okan, ara mo fi won rubo.
Ran ina sori ebo na loni.
Amin.

385 7.7.7.D.
Emi otito ni yio si wa ninu yin. Jn. 14:17.

1 cr Emi Ore, bami gbe!


Emi o si d‘olore,
Pelu oro isore
Ni un o fi emi Re han,
N‘igboya at'irele
L‘emi o soro Kristi

2 di Emi Oto, bu min gbe!


Emi o si d'oloto,
Pelu ogbon to daju
Ni un o fi emi Re han
Ni ife arakunrin
Ni un o s‘oto Oluwa

3 mp Emi Tutu, ba mi gbe!


Emi o si di tutu:
f‘okan mi mo b‘itanna
Li akoko idanwo;
Si sile n‘gba orun nran,
F‘orun, didun yin ‘fe Re

4 mf Emi Ipa, ba mi gbe!


Emi o si lagbara,
Agbara lati bori
Nibi ti ipa eeyan pin,
Un o si ma tesiwaju
Ninu ‗reti titi lae

5 f Emi Mimo, ba mi gbe!


Emi o si di mimo;
Emi o ya fun ese
Emi yan ohun ‘re;
Ohun ti mo ba si ni,
Un o fun Eni to dami.
Amin

386 8s.7s.
Gbogbo won si kun fun Emi Mimo. Ise A. 2:4.

1 f Baba wa orun, a wade,


p Awa alailagbara:
cr Fi Emi mimo Re kun wa
K‘o so gbogbo wa d‘otun
F Wa! Emi Mimo jare wa!
F‘ede titun s‘okan wa
Ebun nla Re ni l‘a ntoro
T‘ojo nla pentikpsti

2 f Ranti ileri Re Jesu,


Tii Emi Re s‘ara wa;
Fi alafia Re fun wa
T‘aye ko le fi fun ni,
F Wa! Emi Mimo, jare wa;
Pa ese run l‘okan wa,
Ebun nla Re ni l‘a ntoro,
T‘ojo nla pentikpsti.

3 f Adaba orun! ba le wa
F Fi agbara Re fun wa;
Ki gbogbo orile ede
Teriba f‘Olugbala,
K‘A gburo Re jakejado
lie okunkun wa yi,
Ebun nla Re ni l‘a ntoro
T‘ojo nla Pentikpsti.
Amin.

387 7,3.7.3.7.7.7.3.
Kiyesi, mo duro li enu ilekun,
mo si nkankun. Ifi. 3:20.

1 mp Alejo kan ma nkan ‘kun


Pe wole,
O ti pe to ti npara;
Pe wole
Pe wole ki o to lo;
Pe wole, Emi Mimo;
cr Jesu Krist‘ Omo Baba
Pe wole.

2 mp Si okan re paya fun,


Pe wole
di B‘o bape y‘o pada lo,
Pe wole
cr Pe wole, Ore re ni;
Yo dabobo okan re,
Yo pa omo de opin;
Pe wole.

3 mp O ko ha gbo ohun Re,


Pe wole
Sel‘ayanfe re loni,
Pe wole,
O duro l‘ehin ‘lekun
cr Yio fun o li ayo
‘Wo o yin oruko Re
Pe wole

4 mf Pe alejo na wole,
Pe wole
Yio se ase fun o
Pe wole
cr Y‘o dari ese ji o
‘Gbati ipinya ba de,
Y‘o mu o dele orun,
Pe wole.
Amin.

388 7.6.7.6.D.
Ongbe re ngbe okan mi,
Bi ile gbigbe. OD. 143:6.

1 mf Emi Mimo sokale,


Fi ohun orun han;
K‘o mu imole w‘aye,
Si ara eniyan
K‘awa t‘a wa l‘okunkun,
Ki o le ma riran,
p ‘Tori Jesu Kristi ku
Fun gbogbo eniyan

2 K‘o fi han pe elese


Ni emi nse papa;
K‘emi k‘o le gbeke mi
Le Olugbala mi
Nigbati a we mi nu
Kuro ninu ese
Emi o le fi ogo
Fun Eni-mimo na.

3 f K‘o mu mi se aferi
Lati to Jesu lo;
K‘o joba ni okan mi.
K‘o so mi di mimo;
Ki ara ati okan,
K‘o dapo lati sin
Olorun Eni-mimo
Meta-lo-kan-soso.
Amin.

389 S.M.&Ref.
Oluwa, mu ise Re Soji. Hab. 3:2.

1 f Ji se Re nde, Jesu
Fi agbara Re han,
ff Fo‘hun to le j‘oku dide,
Mu k‘eniyan Re gbo
F Ji ‗se Re nde Jesu
‘Gba ta nsin O, nihin,
Sokale wa, Olore wa,
Si bukun wa nihin
2 f Ji ‘se Re nde, Jesu,
Mu k‘ongbe Re gbe wa,
Si mu k‘ebi pa okan wa;
Fun onje iye na.

3 mf Ji ‘se Re nde, Jesu,


Gbe oruko Rega,
Mu k‘ife Re kun okan wa,
Nipa Emi Mimo.

4 Ji ‘se Re nde, Jesu,


F‘agbara f‘oro Re,
Ka gbo ‘hinrere ‘bukun Re.
Ni igbagbo aye.

5 cr Ji‘se Re nde, Jesu,


Ro ‘jo itura Re,
ff Ogo yo je Tire nikan,
K‘ibukun je tiwa.
Amin.

390 8.7.8.7. & Ref.


Igbagbo re gba o la. Lk. 7:50.

1 f Nipa igbagbo ninu Krist‘


Awa bo lowo ese.
Nipa gbigbeke l‘oro Re
A bo low‘ ero kero
mf A nfi ‘gbagbo rin l‘okunkun,
A nfi gbagbo tele Krist‘, Imole

2 cr Ona iye ti rorun to,


Ka gbekele Krist‘ nikan;
Aro on Ija re yo pin
Bi iwo ba je gba A.

3 mp Iku Jesu lo san ‘gbese


Ki ‘se ara on ‘ronu,
O ti ru ebi ese wa;
A! fi okan re fun Un.

4 mf A nfi‘gbagbo rin l‘okunkun,


Imo yi ti tobi to;
Ona Olorun pa l‘eyi,
Ma gbekele ero re.
Amin.

391 11.11.11.11. & Ref.


Ki enikeni ti o ba gba A gbo ma ba
segbe sugbon ki o le ni iye
ainipekun. Jn. 3:16.

1 mf Enikeni ti o ba gba Jesu gbo;


To si gba ise ori agbelebu,
Yio ri igbala kikun gba l‘ofe,
F ‘Tori Kristi lagbara lati gbala.
F Eyin ayanfe, Olugbala npe yin
(Ayanfe, Olugbala de, O si npe yin)
(Or‘-pfe ati anu Re je ‘yanu)
(Ore-ofe ati anu Re je ‘yanu)
mp (O ta eje Re Sile fun ‘rapada)
(O ta eje Re sile fun irapada)
F Oun si ni agbara lati gba ni la
(O si ni agbara lati gbala.)

2 cr Enikeni to ba gba ihinrere,


To si gbekele eje Re fun ‘wenu
Yo ri irapada ti ayeraye
F ‘Tori O ni agbara lati gbala.

3 mp Eni to ba ko gbogb‘ ese sile


Ti o si s‘okan re paya f‘Oluwa,
F Yo ni igbala pipe nisisiyi;
‘Tori Oun ti mura tan lati gbala.
Amin.

392 S.M & Ref.


Jesu wipe, Emi li Ona, ati otito ati iye.
Jn. 14:6.

1 mf Jesu wipe Oun li ona,


Emi o si tele;
Mo mo pe lehin okunkun
Imole yo si de.
mf Oun li ona, oto ati iye
Ko s‘ona mi s‘odo Baba af‘odo Re
Oun li ona, oto at‘iye
Ko s‘ona mi s‘odo Baba, af‘odo Re

2 f Oun li oto, oto yo si


Je ‘mole ti nto mi,
Oko mi yo koja okun
Sile alafia.

3 ff Oun ni Iye ko si iku


Ti yo fo mi l‘aya
Nitori nipa eje Re,
Mo ngbe ‘nu Re titi.
Amin.
393 7.7.7.D. & Ref.
Wo o, Odo-agutan Qlorun,
Eniti o ko ese aye lo. Jn. 1:29.

1 mp L ‘ekan mo ba ese ja,


‘Gba t‘o njoba l‘okan mi;
Ti t‘Olugbala fi de
mf O si segun gbogbo won
Nigbat‘ O gbo ebe mi
O si ko ese mi lo.
mf O ko ese mi lo,
O ko gbogbo re,
Kristi Jesu ko ese mi lo,
F Itlorun ti de,
Emi Re ti bori
Bi Jesu ti k‘ese mi lo.

2 f Agbara ise ‘yanu


Ni wakati didun na
Ti Jesu ba mi soro,
Mo gb‘oro ‘yebiye na
Lat‘enu Oluwa mi
‘Gbati O da mi ni ‘de.

3 mf Iwo nja fun rere bi?


Jesu ni gbogbo ipa
Y‘O segun ese fun o.
On y‘O gba agbara re,
On y‘O si ma ba O gbe
Y‘O si fun o ni ‘simi.
Amin.

394 10.7.10.7. & Ref


Kiyesii, emi mbo kankan;
ere mi si mbe Pelu mi. Ifi. 22:12.

1 cr Gba Jesu de lati fere fun wa,


Yala osan tab‘ale,
Y‘o ha ba wa, ka ma foto sona,
K‘atupa wa si ma jo?
Mf A ha le wipe, a se tan, ara,
Fun ‘le wa didan l‘oke?
Wi, y‘O ha ba ‘WO at‘emi nsona?
Nsona, nsona n‘gb‘Oluwa o de?

2 mp Nje bo ba je oro kutukutu,


T‘O ba pe wa ni kokan,
‘Gbat‘ a ba da Talenti wa pada,
Y'O ha wi fun Q, ―o seun?‖
3 di A ha soto s‘eyi t‘O fi fun wa?
Gbogbo ipa wa la nsa?
Ti ko ba si ‘dalebi l‘okan wa
F ‘Simi ologo lao ni

4 mf ‘Bukun l‘awon ti Krist‘ ri to nsona,


Won o pin nin‘ogo Re;
Bi l‘aro tabi oganjo oru
Y‘O ha ba wa be nsona?
Amin.

395 8.5.8.3.
On ni olusesan fun awon ti ofi
arabale wa. Heb. 11:6.

1 mp Are mu o, aye su o,
Lala po fun o?
mf Jesu ni ―Wa si odo Mi,
p Ko simi‖

2 mf Ami wo l‘emi o fi mo
Pe On l‘O npe mi?
p Am‘iso wa lowo ati
Ese Re.

3 mf O Ha ni ade bi Oba
Ti mo le fi mo?
cr Toto ade wa l‘ori Re,
p T‘egun ni.

4 mf Bi mo ba ri, bi mo tele,
Kini ere mi?
p Opolopo iya ati
‘Banuje

5 mf Bi mo tele tit‘aye mi
Kini un o ri gba?
F Ekun a d‘opin un o simi
cr Tit‘aye.

6 mf Bi mo bere pe k‘Ogbami
Y‘O ko fun mi bi?
F B‘orun at‘aye nkoja lo
p Ko je ko.

7 cr Bi mo ba ri bi mo tele,
Y‘O ha bukun mi?
ff Awon ogun orun wipe,
―Yio se‖.
Amin.

396 7.5.7 .6. & Ref


Pelu ipinnu okan,
e fi ara mo Oluwa Ife A. 11:23.

1 mf Duro pelu okan kan,


Se ‘fe Olorun;
Yin awon olotito
Awon egbe Daniel.
cr Se gegebi Daniel;
Ma wo enikan;
Ni ero rere l‘okan
Si je ki aye mo

2 mp Opo akin lo nsegbe


Won ko to duro;
cr Bi won wo egbe Daniel
Won ba ja f‘Olorun.

3 mf Opolopo omiran
Ti nhale kiri
Ni iba subu lule
B‘egbe Daniel ko won.

4 f Gb‘opagun ‘hinrere ga,


E ma segun nso;
Pe ogun esu nija;
Ho ye f egbe Daniel.
Amin

397 7.6.7.6.8.8.8.7 & Ref


E wo iru ife ti Baba fife wa
Jn. 3:1.

1 f Itan iyanu t‘ife!


SO fun mi l‘ekun si,
Itan iyanu t'ife
E gbe orin n aga!
Awon Angeli nroyin Re,
Awon Oluso si gbagbo;
Elese, iwo ki yo gbo
Itan iyanu t‘ife
Ff Iyan! Iyanu! Iyanu!
Itan Iyanu t‘ife

2 Itan iyanu t‘ife


B‘iwo tile sako;
Itan iyanu t‘ife,
Sibe o npe loni;
cr Lat‘ori oke Kalfari,
Lati orisun didun ni,
Lati isedale aye,
Itan iyanu t‘ife.

3 f Itan iyanu t‘ife,


Jesu ni isimi;
Itan iyanu t‘ife,
Fun awon oloto
To sun ni ile nla orun
Pel‘awon to saju wa lo;
Won nko orin ayo orun
Itan iyanu t‘ife.
Amin.

398 7.7.7.7.& Ref.


Nitori ajaga mi rorun,
Eru mi si fuye. Mat. 11:30.

1 f J esu y‘o gba elese


Kede re fun gbogb‘eda;
di Awon ti won sako lo,
Awon ti won ti subu.
ff Ko l‘orin, ko si tun ko
Kristi ngb‘awon elese
Fi oto na ye won pe:
Kristi ngb‘awon elese

2 f Wa, y‘o fun o ni‘simi;


Gbagbo, Oro Re daju,
Y‘o gba eni buru ju;
Kristi ngb‘awon elese

3 cr Okan mi da mi lare,
Mo mo niwaju ofin;
Eni t‘O ti we mi mo,
Ti san gbogbo gbesemi.

4 f Kristi ngb‘awon elese


An‘emi to kun fese
O ti so mi di mimo;
Mo ba wo ‘joba Orun;
Amin.

399 10.10.10.7 & Ref.


E mase je ki Okan yin daru.
Jn. 14:1.

1 mf Aw re mu O, okan re poruru
So fun Jesu, SO fun Jesu;
Ibanuje dipo ayo fun O?
SO fun Jesu nikan.
SO fun Jesu, SO fun Jesu,
On l‘Oro ti o mo;
Ko si Ore
Tabi ‘yekan bi Re
SO fun Jesu nikan.

2 mp Asun-dekun omije lo nsun bi?


SO fun Jesu, SO fun Jesu,
Iwo l‘ese ti enikan ko mo?
SO fun Jesu nikan.

3 p IWO nfoya ‘banuje ti mbe bi?


SO fun Jesu, SO fun Jesu:
Iwo ns‘aniyan ojo ola bi?
SO fun Jesu nikan.

4 p Ironu iku nda o lamu bi?


SO fun Jesu, SO fun Jesu:
O nsaferi ijoba Jesu bi?
So fun Jesu nikan.
Amin.

400 10.6.10.6. & Ref.


Okan mi ti mura, Olorun
okan mi ti mura. OD. 57 : 7.

1 mf Okan mi, a tun fi Jesu lo o


L‘ekan si n‘nu oro Re,
Nisisiyi, Oluwa, un o pinnu
Nki o ha gba Tire?
Mo fe, mo fe
B‘Olorun se ‘ranwo
Emi fe je tire
Eje Re ‘yebiye lo fi ra mi,
Emi yo je Tire

2 mf Nipa or‘-ofe l‘em‘o r‘anu gba,


Mo jere ife Re.
Kristi IWO li emi o gbagbo,
Uno si gbekele O.

3 mp Oluwa, IWO MO ailera mi


Bi nko ti fe sako,
‘WO nikan lo le fun mi l‘agbara
Lati josin fun O.

4 Oluwa f or‘ofe fun wa loni


Ka le jumo'korin:
Ki gbogbo wa SO tokantokan pe,
Emiyo je ti Krist‘.

5 mf Awon to t‘o O wa nigba aye Re


Lati toro ‘bukun,
―Mo fe‖ ni idahun ti won ri gba:
On na la gbokan le.
Amin.

401 C.M. & Ref.


E gba ajaga mi si orun nyin,
enyin o ri isimi fun okan nyin. Mat. 11:29.

1 mp Wa, okan t‘eru ese npa;


Alanu l‘Oluwa;
cr Oun yo si fun O n‘isimi
Bi o ba gbeke le.
Sa gbeke le — (2)
Gbeke le loni,
Yo gba o la — (2)
Yo gba o loni.

2 di N‘tori Jesu ta eje Re


Lati fun O l‘ayo:
cr Wa m‘okun ninu eje na
Ti nso ni di mimo.

3 mf Beni, Jesu l‘oto, l‘ona


Yo f‘isimi fun 0;
Gb‘eke re le, ma jafara;
‘WOO ri ‘bukun gba.

4 f Wa, WO ‘nu egbe mimo yi,


Ka lo sinu ogo,
Lati gbe ilu mimo na
Nibit‘ayo ki tan.
Amin.

402 8.8.8.6. & Ref.


Ebo Olorun ni irobinuje okan.
OD. 51:17.

1 mp Oluwa mi, mo ke pe 0;
Un o ku, b‘O ko ran mi lowo
Mu igbala Re to mi wa,
Gba mi bi mo ti ri,

p Gba mi bi mo ti ri (2)
Kristi ku fun mi l‘ebe mi
Gba mi bi mo ti ri.
2 pp Mo s‘ailokun, ebi mi po;
Ota ‘je Re sile fun mi;
O le se mi b‘O ba ti fe,

3 p Ko si ohun ti mo le se,
Nko le duro ti ‘pinnu mi;
cr Jo, gba mi n‘tori oko Re;
Gba mi bi mo ti ri.

4 p Wo mi, mo wole l‘ese Re;


Semi b‘Oti to loju Re;
S ise Re l‘ase pari,
Gba mi bi mo tiri.
Amin.

403 8.6.8.6.6.6. & Ref.


Nitori Oro Olorun ye,
0 si li agbara. Heb. 4:12.

1 mp E tun won ko fun mi, ki ngbo


Oro ‘yanu t‘iye;
Je ki ntubo gbadun won si
Oro ‘yanu t‘iye,
mf ORO iye didun,
Ti nko ni ni‘gbagbo,
cr Oro didun, Oro 'yanu,
f Oro ‘yanu t‘iye.

2 f Krist‘ Olubukun ti fun wa;


Oro ‘yanu t‘iye;
Elese gbo ‗pe ife na,
Oro ‘yanu t‘iye;
L‘ofe la fi fun wa
O si nto wa s‘orun

3 f Gbe ohun ihinrere na,


Oro ‘yanu t‘iye
Fi ‗dariji lo gbogb‘eda
Oro ‗yanu t‘iye
Jesu Olugbala
So wa di mimo lae
Amin

404 7.6.7.6.D. & Ref.


Oro re ti dun mo mi li enu to!
OD. 119:103.

1 mf ‘Wo Oro dun julo,


To kun fun ileri
Ati imuse pelu
Opin ohun ‘jinle.
p Nigba ekun at‘ayo,
di ‘Yemeji at'eru,
p Mo gbo Jesu wipe, "Wa"
Mo si lo s‘odo Re.
F Wa, wa s‘odo mi;
Wa, wa s‘odo mi;
Alare t‘orun nwo;
Wa, wa s‘odo mi.

2 mp Okan mi; ‘Wo yo se lo


Kuro lod‘ore yi,
Sa sunmo timotimo;
Bagbe titi d‘opin;
p O se; ailera mi po,
Mo kun f‘ese pupo
N‘tor‘emi ko le sako;
Lehin mo ba pada.

3 mp Ma mu mi sunmo ‘do Re
Ki ―Wa‖ na ba ‘le je
Ohun ti a fo jeje
F‘enit‘o sunmo O;
Mo mbe l‘oke tab‘odo,
L‘okere nitosi,
Emi o ma tele O,
‘Gba mo ba gbo pe,―Wa‖
Amin.

405 8.7.8.7.& Ref.


Emi wa pelu nyin nigbagbogbo.
Mat. 28:20.

1 Onisegun nla wa nihin,


Jesu abanidaro;
Oro Re mu ni l‘ara da,
A gbo ohun ti Jesu.
F Iro didun l‘orin Seraf‘,
Oruko didun li ahon;
Orin to dun julo ni:
di Jesu, Jesu, Jesu

2 mp A figbogb‘ese re ji o,
A gbo ohun ti Jesu.
cr Rin lo s‘orun l‘alafia
Si ba Jesu de ade.

3 f Gbogb‘ogo fun Krist‘ t‘O jinde


Mo gbagbo nisisiyi;
Mo f‘Oruko Olugbala,
Mo fe Oruko Jesu.

4 Oruko Re l‘eru mi lo,


Ko si oruko miran:
B‘okan mi ti nfe lati gbo
Oruko Re ‘yebiye

5 f Arakunrin eba mi yin,


E yin oruko Jesu;
Arabirin, gb‘ohun soke,
E yin oruko Jesu.

6 Omode at‘agbalagba
T‘o fe oruko Jesu
Le gba pe ‘fe nisisiyi
Lati sise fun Jesu.

7 Nigbat‘ a ba si de orun
Ti a ba si ri Jesu;
A o ko ‘rin yi ‘te ife ka,
Orin oruko Jesu.
Amin.

406 C.M.
Emi ni Olorun Olodumare:
ma rin niwaju mi,
ki iwo ki o si pe Gen. 17:1.

1 mp K i n‘ireti ipe wa je
Leyin iwa-mimo?
Fun eyi ni mo nwo Jesu,
Ti mo si duro je.

2 cr Mo duro, tit‘On yo we mi,


Ti yo fiye fun mi,
At‘igbagbo ti nle ese
Ti nso ‘kan di mimo

3 mf Or‘ofe ‘rapada l‘eyi,


Ofe ni felese;
Loto yo se lori emi
Olori elese

4 p On yo ra okan mi pada.
Kuro n‘nu gbogb‘ese;
Mo gba Jesu gbo nitoto.
Mo fi ara mi fun.

5 mp Nigba Jesubangbe‘numi,
Gbogb‘ese mi yo lo;
f O wipe, Wo! Mo mbo kankan
Lati kun okan re.

6 mf Ko ri gegebi Oro Re!


Gba mi lowo ese,
Okan mi nfe lati gba O,
Wole, Oluwa mi!
Amin.

407 12.8.12.8 & Ref


Bi enikeni ba wa ninu Krisit,
O di eda titun. II Kor. 5:17

1 f Iyipada ‗yanu l‘aye mi lati se


‗Gba Jesu wonu okan mi;
Ff Imole nla ti de ti mo ti nwa kiri
‗Gba Jesu wonu okan mi
F ‗Gba Jesu wonu (wonu) okan mi,
‗Gba Jesu wonu (wonu) okan mi
Odo ayo nsan l‘okan mi b‘igbi okun
‗Gba jesu wonu okan mi

2 mp Mo ti f‘opin si‘rinkiri ati‘sina,


‘Gba Jesu wonu Okan mi;
Ese mi to si po lati fonu kuro,
Gba Jesu wonu okan mi.

3 mf Mo ni‘reti kan to ni idaniloju,


Gba Jesu wonu okan mi;
Ko sohun to le mu mi siyemeji mo,
‘Gba Jesu wonu okan mi.

4 f Emi yo si ma gbe ni ‘lu na ti mo mo,


‘Gba Jesu wonu okan mi;
Inu mi si ndun, mo si nyo bi mo ti nlo.
‘Gba Jesu wonu okan mi.
Amin

408 10.11.10.8.D.
Jesu si wifun u pe, Riran;
igbagbo re gba o la Lk. 18:42.

1 cr Afoju agbe na, wa leba ona


Titi Jesu fi wa, to wa s‘ona na;
F Inure si dun s‘agbara Olorun,
'Gba Jesu gb‘ona na koja.
cr Ebi on ese njoba laye mi,
Ki Jesu ko to gba ona mi koja;
mf Nisisiyi ayo at‘alafia de,
‘Gba Jesu gb‘ona mi koja.

2 mf Gbolohun kan lat‘enu Oluwa


Lo l‘agbe na loju, gba Jesu nkoja;
Igbagbo agbe na nin‘oro na
Fi imole kun okan re.

3 f Mo gbo iro didun ti angeli,


‘Gba Jesu nkoja to ngb‘ona mi koja;
Bi won ti nfayo korin ‘rapada
‘Gba Jesu ngb‘ona mi koja.

4 mf Elese wa sodo Olugbala,


Ka we o nu kuro ninu ese re;
Jeki ‘mole Oluwa wonu re,
Gba Jesu gb‘ona yen koja.
Amin.

409 11.11.11.11.10.9.11.11.&Ref.
Awa o tun nkan yi gbo
li enu re. lse. A. 17:32.

1 mp So fun wa b‘o ti se gba idariji?


Awa tun nfe gbo itan na lekan si:
Bo se wa sib‘agbelebu fun ‘gbala,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si:
O ha nrin n‘nu‘mole ibukun Re?
O ha bo ninu ebi gbogbo?
mf Krist‘ ha je ayo, orin re n‘gbagbogbo?
Awa tun nfe gbo itan na lekan si.
mf Jo, tun itan na so fun wa,
(Jo tun itan na so fun wa lekan si)
Tun itan na so fun wa,
(Jo, tun itan na so fun wa lekan si)
F Itan didun ti ibukun,
Yio ran o lowo de ogo;
Awa tun nfe gbo itan na lekan si.

2 mf So fun wa: Jesu ha mba o sise bi?


Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
Sp fun wa: O ha ngbe o li apa Re?
Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
Ko tun si ore, ti o dabi Re
To le mu o la isoro ja;
F Jek‘ araye gbo ohun t‘O se fun o
Awa tun nfe gbo itan na lekan si.

3 mf O ha ti korin ‘bukun bi eyi ri?


Awa tun nfe gbo itan na lekan si:
F Orin ti o dun ju ala didun lo,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
Opo lo ti nwa isimi kiri,
T‘ibanuje gori okan won,
F Kede Jesu fun won l‘oro tab‘orin;
Awa tun nfe gbo itan na lekan si.

4 mp So t‘ijakadi re at‘isegun re,


Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
Yo ran awon to sese gbagbp LOWO,
Awa tun nfe gbo itan na lekan si;
cr Ogun orun apadi la mba ja,
Laipe a o ba Jesu joba,
Eyin ta ra pada, e mu eso wa
Awa tun nfe gbo itan na lekan si.
Amin.

410 11.10.11.11. & Ref


O je ki o mu oyin lati inu apata wa.
Deut. 32:13.

1 p N in‘ aginju ese, Jesu wa mi ri,


Ninu ogbun ese. ainireti;
Jeje lona idariji l‘O nto mi,
O si nfi onje bo mi li aginju.
mf Pel‘oyin ‘n‘apata lo fi mbo awon Tire,
Oyin didun lati ‘nu apata,
Pel‘oyin ‘n‘apata l‘O fi mbo awon Tire,
Didun l‘ebun olprun.

2 f Ninu oro ore ofe lo nfun mi


Ni ‘bukun ‘yanu lo mayo mi kun,
‘ Jojumo lo nfi ‘sura Re bokan mi
Oyin, waru at‘eso to daraju.

3 ff A ko le so gbogb‘ayo ti 'rapada,
A ko le so ‗daji ‘sura‘bukun;
A ko le so won ‘bukun to wa n‘nu nini
Imo 'dariji at‘alafia lae.

4 mp Wa, elese, ipe nla ni eyi je,


Wa pel‘okan t‘eru npa;
Ki o ba le ni ipin ninu ayo
Ta se l‘eri re fun awon oloto.
Amin.

411 7.7.7.7.7.7.
A ko fi ohun ti idibaje ra
nyin pada bikose eje Jesu....
I Pet. 1:18-19.
1 mf Jesu f‘eje Re ra wa.
Eje k‘a sunm'Olorun;
Opo nsina yi wa ka;
di K‘anu mu wa gbadura,
Pe ki awon t'o fo ‘ju,
Laipe le r‘ona oto.

2 mf Oluwa, Ji won yika,


Ki won mo ‘pe ayo na;
Eru esu leekan ri,
di Ma jeki won s‘eru mo;
Oluwa, awa nwo O;
D'elese ‘gbekun sile.

3 mf A gbo ‘royin ogo Re,


Ohun t‘apa Re ti se;
Opo so t‘ipa Re,
F A ba tun le ri sa ni!
Mu won soji, Oluwa;
Ipa lyin na Tire.
Amin.

412 C.M.
Yara lati ran mi lowo
Oluwa igbala mi: OD. .18:22.

1 mp Wa, Oluwa l‘anu tun wa,


Pelu ‘pa 'p‘okan da;
Ongbe ojo np‘oko Sion,
Masai ro s‘ori re.

2 p Okan wa kun fare kikan,


Lati ri b‘elese,
Ti nte si iku ailopin,
Li airi iranwo.

3 p ―Jesu, wa pelu‘pa‘soji,‖
L‘awon eeyan Re nke
Mu ‘gbala wa ni sa anu,
Majek‘ elese ku.

4 mf Jek‘ elese ro s‘ile Re,


Ki won ho isegun.
cr Gbana l‘edun wa y‘o d‘ayo.
Ekun, d‘orin iyin.
Amin.

413 L.M.
On o si fun nyin ni olutunu miran.
Jn. 14:16.
1 mp Gbo l‘or‘ ite Re. Alade,
F‘oniruru ‘bukun ranse,
B‘awon omo Re ti nwa O,
Gb‘adura t‘oro Re ko ni.

2 mp Wa, Emi Mimo lat‘oke,


F‘ife kun okan t‘o tutu;
A! s‘okan okuta d‘eran,
K‘O jek‘ ipa Re di mimo.

3 p Soro, oju t‘o da yio sun


Ekun ‘robinuje jade;
Won yo si figbona okan
Wa ore ti won ko nani.

4 mf A! jek‘opo awon mimo


Duro n‘ilekun ile Re;
di K‘olukuluku se ‘tara
Lati f‘ara rubo fun O.
Amin.
414 L.M.
Bi enikeni ba gbo ohun mi,
ti o si si ilekun, emi o si
Wole to O wa. Ifi. 3:20

1 mf Ara n‘nu Krist‘, nitori Re,


A fi t‘okan-tokan gba O;
K‘a le jumo je ayo ti
Ko s‘en‘ti fun ni lehin Re

2 K‘Enit‘a pe nipa‘ke Re,


p Ran Emi ‘re Re sokale,
k‘O jeki ede wa k‘o dun,
K‘okan wa gbona fun ife.

3 Gb‘onigbagbo ba pe bayi,
Ero aye a d‘igbagbe;
A nfe lati s‘oro en‘t‘o
Ku, t‘O joba fun wa nikan.

4 p Ao, sO t‘ise at‘oro Re,


T‘iya t‘Oje fun wa l‘aye,
T‘ona t‘O la fun rinrin wa,
T‘ohun t‘O nse lowo fun wa.

5 mf Bi akoko ti nrekoja,
A o feran so sin n‘iyanu;
Ma reti ojo ogo ni
Ti ao pe li aipinya mo.
Amin

415 7.7.7.7
Olorun re niyio ma se
Olorun mi. Rutu 1:16.

1 mp Eyin eeyan Olorun,


Mo ti kiri aye ka,
To ‘pa ese on ‘kanu,
Nko r‘itunu n‘ibikan.

2 Okan mi pada si yin,


Emi isansa, mo de;
Nibi pepe yin ba njo,
E jo, gba mi s‘isimi.

3 Emi k‘yo nikan rin mo


Bi ategun at‘igbi;
‘Bugbe yin yo je ‘le mi,
‘Busun yin, iboji mi.

4 f T‘emi ni Olorun yin;


Jesu yin yio je t‘emi;
Aye kole tun fa mi;
Mo ko gbogb‘ osa sile.
Amin.

416 C.M.
E mase fe aiye. 1 Jn. 2:15
1 mf Awa fe ohun aye yi,
Won dara l‘oju wa;
A fe k‘a duro pe titi
Laifi won sile lo

2 Nitori kini a nse bee?


Aye kan wa loke;
Nibe l‘ese on buburu
Ati ewu ko si.

3 Aye t‘o wa loke orun,


Awa iba je mo!
Ayo, ife, inu rere,
Gbogbo re wa nibe

4 p Iku, o wani aye yi;


Ko si loke orun;
Eniyan Olorun wa mbe,
Ni aye, ni aiku.

5 K‘a ba ona ti Jesu lo,


Eyi t‘O la fun wa;
ff Sibi rere, sibi ‘simi,
cr S‘ile Olorun wa.
Amin.

417 11.11.11.6. & Ref


Biko sepe a tun eniyan bi,
on ko le ri ijoba Olorun. Jn. 3:3.

1 mf Ijoye kan to Jesu wa li ale,


Lati bere ona ‘gbala on ‘mole;
Olukoni dahun l‘oro oto pe,
mp ―Ao le sai tun yin bi‖
cr Ao le sai tun yin bi‖ (2)
Otito li oro na ti mo so pe:
Cr ―A o le sai tun yin bi‖

2 mp Eyin omo eniyan, e gbo oro


Ti Jesu Oluwa so pelu edun
Mase je k‘oro na bo s‘asan fun yin
Ao le sai tun yin bi.

3 mf Eyin te nfe de ‘bi simi ogo yi


Lati ba awon mimo korin 'bukun:
Bi e ba fe gba lye ainipekun
Ao le sai tun yin bi

4 mp Olufe t'okan re nsaferi jojo


Le ma w‘ona re ni ibode orun;
Nje fetisi ohun orin jeje yi:
P Ao le sai tun yin bi
Amin.

418 12.12.12.6.D.
Emi o si bere lowo Baba,
On O si fun yin li Olutunu
miran Jn. 14:16.

1 f Tan ihin na kale, jakejado aye,


K‘awon ti eru npa, mo pe igbala de:
mf K‘awon ti se ti Krist‘, so ihin ayo na,
Olutunu ti de.
mf Olutunu ti de, Olutunu ti de,
Emi lat-oke wa, ileri Baba wa;
F fan ihin na kale, jakejado aye,
Olutunu ti de.

2 mf Oba awon oba, wa fiwosan fun wa,


O wa ja ide wa, O mu igbala wa,
K‘olukuluku wa, korin isegun pe: Olutunu ti de.
3 ff Ife iyanu nla, a! mba le royin na,
Fun gbogbo eniyan, ebun or‘-ofe Re;
mf Emi omo egbe, di omo igbala,
Olutunu ti de

4 f Gbe orin ‘yin soke, s‘Olurapada wa,


K‘awon mimo loke, jumo ba wa gberin
ff Yin ife Re titi, ife ti ko le ku,
Olutunu ti de.
Amin.

419 L.M.
Nwon o ma Soro ogo ijoba Re,
n won o si ma soro agbara Re.
OD. 145:11.

1 mf Emi anu oto, ife,


Ran agbara Re toke wa;
cr Mu lyanu ojo oni
De opin akoko gbogbo.

2 f Ki gbogbo orile ede


Ko orin ogo Olorun;
Ki a si ko gbogbo aye
N'ise Olurapada wa.

3 mp Olutunu at‘Amona,
cr Joba Ijo Eniyan Re;
mf K'araye mo ibukun Re,
Emi anu, oto ife.
Amin.

420 7.7.7.7.D.
Oluwa, Olorun Olodumare
njoba. Ifi. 19:6.

1 f Gbo! orin ti Jubeli,


O dabi sisan ara;
Tabi bi kikun okun,
‘Gbat‘ igbi re ba nlu ‘le;
ff Aleluya! Olorun
Olodumare joba;
ff Aleluya! k‘oro na
Dun yi gbogbo aye ka.

2 f Aleluya! gbo iro


Lati aye de orun,
Nji orin gbogbo eda,
L‘oke, n‘isale, yika,
Wo Jehofa ti sete,
p Ida w‘ako; O pase,
Awon ijoba aye
Di ijoba Omo Re.

3 Yo joba yi aye ka,


Pelu agbara nlanla;
Yo joba‘gbati orun
At‘aye ba koja lo:
p Opin de: lab‘opa Re
pp L‘ota eniyan subu:
ff Aleluya! Olorun
Ni gbogbo l‘ohun gbogbo.
Amin.

421 7.6.7.6.D
Lojojumo li a o si ma yin I.
OD. 72:15.

1 f Alafia fun Jesu


Omo nla Dafidi.
Ni akoko ti a yan,
N'igba Re bere;
Mf O de lati tan iya,
Lati tu igbekun,
Lati mu ese kuro.
Yo joba l‘aisegbe

2 mf O mbo wa pelu‘ranwo,
Fun awon ti njiya,
Yo ran alaini lowo,
Yo gb‘alailera ro;
cr Yo f‘orin dipo ose,
Okun yo di ‘mole
F‘okan ebi ti nku lo.
To s‘owon loju Re.

3 mp Yo s‘okale bi ojo
Sori ile aye:
Ife, ayo, ireti,
So jade l‘ona Re;
mf Alafia yo kede Re
Lori awon oke,
Ododo b‘isun omi
Yo toke san sile.

4 di Araba, alarinkiri,
Yio wole fun U;
Alejo Etiopea
Yio wa w‘ogo Re:
mf Oko okun o pade
Pelu ore isin:
Lati f‘isura okun
Josin lab‘ese Re

5 mp Oba yio wole fun


T‘awon ti turari
Gbogbo orile ede
Yo korin iyin Re
mf Lojojumo l‘adura
Yio ma goke lo;
Ijoba Re yo gb‘ile
Ijoba ailopin.

6 f Yo segun gbogbo ota


Yo joko n‘ite Re;
Ogo Re yio ma ran,
Alabukun laelae
mf Ayida aye ko le
Mu majemu Re ye,
Ife li oruko Re.
Ki o pada laelae
Amin

422 L.M.
Ji, ji, gbe agbara WO,
Iwo apa Olorun. Isa. 51:9.

1 f Ji, apa Olorun, ko ji,


Gbe ‘pa Re wo, mi orile
Ni sisin Re, je k‘aye ri
Isegun ise anu Re.

2 ff T‘ite Re wi fun keferi,


―Emi Jehofa Olorun‖
Ohun Re yo d‘ede won ru,
Yio wo pepe won lule.

3 mf Ki ‘gb‘ojurere Sion‘ de,


Ka m‘eya Israel‘ wa ‘le;
N‘iyanu ka foju wa ri
Keferi, Ju, l‘agbo Jesu.

4 f Olugbala kede‘fe Re
L‘orile at‘ede gbogbo;
Ki gbogb‘ ota wole fun O
Ki won gba Jesu l‘Oluwa.
Amin.

423 7.6.7.6.D.
Wa, ki o si ran wa lowo
lse. A. 16:9.

1 mf Lat‘oke tutu Grinland,


Lati okun India;
Ni b'odo orun Afrik‘
Nsan 'yanrin wura won;
Lat‘ opo odo ‘gbani;
Lati igbe ope,
Wpn npe wa k'agba le won,
L‘ewon sina won.

2 Afefe orun didun,


Nfe je ni Srilanka;
Bi ohun ta nri dara.
di Eniyan lo buru;
mp Lasan, lasan l'Olorun
Nt‘ebun Re gbogbo Ka!
Keferi, ni ‘foju won
Nwole bo okuta.

3 mp Nje awa ti a moye


Nipa ogbon orun,
O to ka f‘imole du
Awon to wa l‘okun
ff Igbala A! Igbala!
Fon rere ayo na
Titi gbogbo orile
Yoo mo Messiah.

4 f Efufu, mu ‘hin re lo,


Ati eyin odo,
Titi bi okun ogo
Yo tan yi aye ka;
Tit‘Odagutan ta pa
Fun irapada wa
ff Yio pada wa joba,
Lalafia laelae.
Amin.

424 L.M.
Wasu oro na. II Tim. 4:2.

1 mf Keferi nsegbe l‘ojojo,


Egbegberun lo nkoja lo;
F Mura Kristian s‘ igbala won.
Wasu fun won, ki won to ku.

2 f E yonda owo, at‘ebun


At‘emi yin, ki won le ye;
Jesu se ohun nla fun yin,
Kil‘ohun te ki o se fun.

3 Emi Oluwa, fo kiri,


Jake-jado ile aye;
Ko awon om‘Olorun jo
Lati gbogbo oril‘-ede.
Amin.

425 L.M.
E ma po si i ni ife
Oluwa nigba gbogbo.
IKor. 15:58.

1 f Ma sise lo, mase sare,


Fi ayo sise Baba re,
Bayi ni Jesu se l‘aye:
Ko ha ye k‘awa ko se be.

2 Ma sise lo ki se lasan,
Ofo aye l‘ere orun:
Bi araye ko fe yin o.
Iyin Jesu ju t‘eda lo.

3 f Ma sise, l‘ojojumo,
p Okunkun aye fere de;
f Mura si ‘se, mase s‘ole,
Ko ba le gba okan re la.

4 p Pupo, pupo l‘awon to ku,


Ti won ko n‘ireti orun,
Gbe ina ‘gbagbo re, ma fi;
Ma fi si okunkun aye.

5 Ma sise lo, ma gbadura:


F‘ogbon wa awon to sina;
Jade lo s‘opopo ona,
Ro asako lati wole.

6 f Ma sise lo, ma yo pelu


Lehin ise ‘wo o simi;
O fere gb‘ohun Jesu na;
ff Y‘O ke tantan pe, ―Emi de‖.
Amin.

426 6.6.4.6.6.6.4.
Olorun si wipe. "Jeki imole
ki o wa‖, imole si wa. Gen. 1:3.

1 f Iwo ti okunkun
Gb‘oro agbara Re,
cr To si fo lo:
p Gboti wa, a nbe O,
Nibit‘ ihinrere
Ko ti tan mole re,
F K‘imole wa.

2 mf ‗Wo t‘iye apa Re


Mu iriran w‘aye,
cr At‘ilera:
p Ilera ti inu;
Iriran ti okan;
Fun gbogbo eniyan
F K‘imole wa.

3 mp Iwo Emi oto,


Ti o n f‘iye fun wa,
cr Fo kakiri:
Gbe fitila anu
P Fo ka oju omi,
Ni ‗bi okunkun nla,
F K‘imole wa

4 f Metalokan Mimo,
Ogbon, ife, Ipa,
Alabukun!
Ff B‘igbi omi okun
Ti nyi ni ipa re,
Be ka gbogbo aye,
K‘imole wa
Amin.

427 11.11.11.11
Olorun tikarara si wa
pelu wa li Olori wa.
IIKro. 13:12.

1 ff Gbo iro efufu lat‘ ona jinjin,


O nsoro ‘jakadi ti ogun mimo;
Olorun mbe fun wa. O ti soro Re,
O si nso gbogbo yin, Ojise orun.

2 mf Lo! ‘wo ihinrere, ma segun titi,


Okunkun ndimole ni gbogbo aye;
O sa wole fun O, ile won si wo,
Gbogb‘eda bu jewo pe ‘Wo l‘Oluwa.

3 f Olugbala mimo ti njoba loke,


K‘awon om‘ogun Re ma ri O titi;
Je k‘oro Re ma tan lat‘ile de ‘le,
Ki gbogbo agbaye teriba fun O.
Amin.

428 6.6.6.6.
Ki ijoba Re de.
Mat. 6:11.

1 mf Krist‘ ki ‗joba Re de,


Ki ase Re bere;
F‘opa irin Re fo
Gbogbo ipa ese

2 p Ijoba ife da?


Ati t‘alafia;
‘Gba wo ni irira
Yio tan bi t‘orun?

3 Akoko na ha da
T‘ote yio pari;
Ika ati ‘reje,
Pelu ifekufe?

4 mp Oluwa, jo dide
Wan‘nu agbara Re;
Fi ayo fun awa
Ti o ns‘aferi Re.

5 p Eda ngan oko Re,


Koko nje agbo Re,
Iwa ‘tiju pupo
Nfihan pe ‘fe tutu.

6 Okun bole sibe,


Ni ile keferi,
cr Dide‘Rawo oro,
ff Dide mase wo mo
Amin.

429 13.6.13.6.13.13.13.15.13.6.13.6.
E wi larin awon keferi pe
Oluwa joba OD. 96:10.

1 Wi jade larin keferi p'Oluwa l‘Oba,


Wi jade! Wi jade!
Wi jade forile-ede mu ki won korin,
Wi jade! Wi jade!
cr Wi jade tiyin tiyin pe, On o ma po si,
Pe, Oba nla Ologo l‘Oba alafia,
ff Wi jade tayotayo bi iji tile nja
Pe O joko lor‘isan omi, Oba wa titi lae.
2 Wi jade larin keferi pe, Jesu njoba,
Wijade! Wijade!
cr Wi jade f‘orile-ede mu k‘ide won ja,
Wijade! Wijade!
p Wi jade fun awon ti nsokun pe, Jesu ye,
Wi jade f‘alare pe, O nfun ni n‘isimi,
Wi jade f‘elese pe O wa lati gbala;
Wi jade fun awon ti nku pe, O ti segun
iku.

3 f Wi jade larin keferi Krist‘ njoba loke,


Wijade! Wijade!
Wi jade fun keferi ife n‘ijoba Re,
Wijade! Wijade!
cr Wi jade l‘ona opopo l‘abuja ona
Je ko dun jakejado ni gbogbo agbaye,
ff B‘iro omi pupo ni k‘iho ayo wa je,
Titi gbohun-gbohun yo fi gbe iro na
de'kangun iye
Amin.

430 8.7.8.7.D.
Nitori mi ati nitori ihinrere.
Mk. 8:35.

1 f Tori Mi at‘Ihinrere,
E lo so t‘Irapada,
cr Awon onse Re nke, ―Amin‖
f Tire ni gbogbo ogo;
mf Nwon nso t‘ibi, t‘iya, t‘iku,
Ife etutu nla Re;
Nwon ka ohun aye s‘ofo
F T‘ajinde on'joba Re

2 f Gbo, gbo, ipe ti Jubeli,


O ndun yi gbogb‘aye ka,
cr N‘ile ati l‘oju okun,
A ntan ihin igbala;
p Bi ojo na ti n sun mole,
T‘ogun si ngbona janjan,
F Imole ila-orun na
Yo mo larin okunkun.

3 f Siwaju ati siwaju


Lao ma gbo, ―Aleluya‖
cr Ijo Ajagun yo ma yo
Pel‘awon oku mimo,
A fo aso won n‘nu eje,
Duru wura won si ndun,
ff Aye at‘orun d‘ohun po,
Won nko orin isegun.

4 f O de Eni t‘a nwona Re,


Eni ikehin na de.
Imanueli t‘O d‘ade,
Oluwa awon mimo,
cr lye, Imole at‘ife,
Metalokan titi lae;
ff Tire ni ite Olorun
Ati t‘odo Agutan.
Amin.

431 L.M.
On o joba lot'okun de okun.
OD. 72:8.

1 f Jesu yo joba ni gbogbo


Ibit‘aba le ri orun:
‘Joba Re yo tan kakiri,
‘Joba Re ki o nipekun.

2 mf On li ao ma gbadura si,
Awon oba yo pe l‘Oba;
Oruko Re b‘orun didun
Y‘o ba ebo oro g‘oke.

3 Gbogbo oniruru ede,


Yo fi ‘fe Re korin didun;
p Awon omode yo jewo,
Pe ‘bukun won t‘odo Re wa.

4 f ‘Bukun po nibi t‘On joba,


A tu awon onde sile,
Awon alare ri ‘simi,
Alaini si ri ‘bukun gba.

5 ff Ki gbogbo eda ko dide,


Ki won f‘ola fun Oba wa;
K‘angel‘ tun wa t‘awon t‘orin
Ki gbogb‘aye jumo gberin.
Amin.

432 6.6.6.6.8.8.
0 ti ran mi lati kede idasile
fun awon igbekun. Isa. 61:1.

1 f E fun ‘pe na kikan,


Ipe ihinrere;
K‘o dun jake jado
L‘eti gbogbo eda:
ff Odun idasile ti de
Pada elese, e pada.

2 Jesu Alufa wa
Ti s‘etu lasepe:
Alare, e simi,
Asofo, tujuka.

3 mf Fun‘pe t‘od‘agutan
Tati pa setutu;
cr Je ki agbaye mo
Agbara eje Re

4 Eyin eru ese;


E so ra yin d‘omo;
Lowo Kristi Jesu,
E gb‘ominira yin.

5 f Gbo ‘pe ihinrere,


Ihin ore-ofe;
Agba yin low‘aye,
E wa ‘waju Jesu.
Amin.

433 L.M.
Emi yio tu ninu Emi
mi sara eniyan gbogbo. Ise A. 2:17.

1 f Emi Olorun alaye,


N‘nu ekun ore-ofe Re,
Nibit‘ ese eeyan ti te,
Sokale s‘ori iran wa.

2 mf F‘ebun ahon, okan ife


Fun wa, lati Soro‘fe Re;
K‘ibukun at‘agbara Re
Ba l‘awQon to ngbo Oro na.

3 K‘okun ka ‘se ni bibo Re;


Ki ‘daru dapo di tito;
F‘ilera f‘okan ailera,
Je ki anu bori ‘binu.

4 mp Emi Olorun, jo pese


Gbogbo aye fun Oluwa,
cr Mi si won b‘ afefe oro,
K‘okan okuta le soji.

5 f Baptis‘ gbogb‘ orile-ede,


Royin ‘segun Jesu yika;
Yin oruko Jesu l‘ogo;
Tit‘araye yo jewo Re.
Amin.

434 8.8.8.6.& Ref.


E ji iji ododo. IKor.l5:34.

1 f Ji, so agbara Re d‘otun


Gbe ‘hamora ogun re WO;
A o segun gbogbo ota,
Kristi yo si joba.
ff Krist‘ y‘o joba
Krist‘ y‘o joba,
Ireti wa n‘nu Re ko ye;
Krist‘ y‘o joba,
Krist‘ y‘o joba,
Krist‘ y‘o joba,
Ireti wan‘nu Re ko ye
Krist‘ y‘o joba.

2 mp O ti pe t‘awon Omo Re
Ti nse ‘yapa lori eko;
Won gbagbe pe l‘ori ‘sokan
Ni On lo aye Re.

3 mf E papo li agbara Re,


Aye yin yo ,si je ere;
F Laipe e o ni isegun,
‘Tori Krist‘ y'o joba.

4 cr O ye ka sise f‘Oluwa,
Ise wa ko ni je asan;
mf A ko gbodo pada s'ehin,
‘Tori Krist‘ y‘o joba.
Amin.

435 7.6.7.6.D
Kristi si ni ori Ijo
Re Efe. 5:23.

1 f Jesu Oluwa ni ‘se


Ipinle Ijo Re,
Omi ati oro Re
Ni On si fi tun da;
O t‘orun wa, O fi se
Iyawo mimo Re,
mp Eje Re lo si fi ra
p Ti O si ku fun un.
2 Nile gbogbo la sa won,
Sugbon won je okan;
Oluwa kan gbogbo kan
Ati baptisi kan:
F Oruko kan ni won yin,
Onje kan ni won nje;
Opin kan ni won n lepa,
Nipa ore ofe

3 Bi aye tile nkegan,


‘Gbat‘ iyonu de ba:
B‘ija on eko keko
Ba mu iyapa wa;
Awon mimo yo ma ke
f Wipe, ―yo ti pe to?‖
Oru ekun fere di
Oro orin ayo.

4 di L‘arin gbogbo‘banuje
At‘iyonu aye,
Onreti ojo ‘kehin
Alafia lae lae;
Titi yo foju Re ri
Iran ologo na!
Ti ijo nla, asegun
Yo d‘ijo ti nsimi.

5 mf L‘aye yio ni‘dapo


Pelu Metalokan;
Osi ni‘dapo didun
Pel'awon to ti sun;
F A! alabukun mimo!
Oluwa fi fun wa,
Ka ba le ri bi awon,
Ka ba O gbe l‘orun.
Amin.

436 D.C.M.
Ki ife ara Ki o wa titi. Heb. 13:1.

1 f Ife Olugbala a o f‘ayo han,


Ki gbogb‘ aye le ri,
Ayo 'simi, alafia
T'awon lo t'e O ni.
mf Gbogbo aye, gbogbo aye,
Gbogbo, tile, t‘okun (toke),
A fe gbogbo aye fun Krist‘
K‘orile d‘ominira.

2 mf Je ki le soro ‘hinrere
Titi gbogb‘ okan wa
Pelu gbogb‘ eni yi wa ka
Y‘o fi gba O l‘Oba.

3 f Ran wa b‘ina at‘orun wa,


Ti mole re yo tan,
Tit‘awon to wa n‘n‘okunkun
Yo ri imole na.

4 mf Je ki ‘yanu or‘ofe Re
Kun inu okan wa;
K‘awa le fi itara lo
Lati se ‘ranlowo.
Amin.

437 7.7.7.7
Oluwa joba; ki aye ki oyo.
OD. 97:1.

1 mf Oluwa joba aye,


Korin ‘yin, eyin eda;
E korin tayo-tayo,
Jesu Messiah joba!

2 f Jesu la f‘agbara fun,


Oluwa gbogbo aye,
Gbogb‘ ekun y‘o wole fun:
Esu , gbo, k‘o wariri!

3 ff K‘awon angel‘ d‘ohun po


Ki won se ajoyo na;
Ki won jumo yin
Jesu Ki won kede ‘segun Re

4 mf B‘omo okunkun sata,


Awon tiwa ju won lo
Olorun mbe ko si nkan;
Kristi mbe k‘ota damu.

5 f E foju igbagbo wo,


B‘awon oke ti mole;
Olorun mbe nitosi,
O fi ‘mole yi wa ka.

6 mf Olugbala sokale,
O ntoka s‘ade ‘segun,
O npe wa sipo loke,
O fe wa j‘asegun lo.
Amin
438 7.6.7.6.7.7.7.6
Eni-nla ni Oluwa. OD. 48:1.

1 f Eni nla l‘Olugbala


Ninu olanla Re;
On l‘awon torun njuba,
Ijo Re l‘aye nyin;
Ni ilu Olorun wa,
Loke mimo Re laye,
mf Kede oko Re k‘aye
Fi titobi Re han.

2 cr Nitor‘iseun ife Re,


A duro n‘ile Re;
Nihin f‘oto ‘fe Re han,
F‘ipa ‘gbala Re han:
A mo ‘yin Re l‘oko Re,
Pipe ewa Re logo;
mp Gbogbo aye yo jewo
Pe, mimo n‘ise Re

3 mf Ijo Re mbe lailewu,


O duro l‘apata;
Gbogbo ‘leri re daju;
Tani le si n‘idi?
Kiyes‘ awon ofin Re
So f‘awon ‘ran ti mbo, pe,
F Ijo na ko le baje
Lagbara Oluwa.

4 f Tiwa l‘Olorun Sion,


A simi le‘fe Re;
Amo p‘O ndariji ni,
Ti Kristi li a se:
On y‘o se Oluto wa,
Si Jerusalem titun;
mf On l‘Enit‘a simile,
Titi ayeraye.
Amin.

439 7.7.11 .D. & Ref.


Ma ja ija rere ti igbagbo.
1 Tim. 6:12.

1 f Gbe asia na soke!


Si ma gbe lojojumo,
Titi gbogb‘ agbara ibi yo wole!
F Jeki o ma fe lele
Pelu ‘hin Krist‘ le gbala;
Gbe soke titi yo fi yi aye ka.
F Gbe soke titi yo fi yi aye ka,
Titi agbara nla ibi yio fi wo;
Jeki o ma fe lele.
Pelu ‘hin: Krist‘ le gbala,
Gbe soke titi yo fi yi aye ka.

2 mf Gbe asia, na soke,


Ni gbogb‘ orile ede,
Ki a ma se ka asia na kuro;
f Titi aye yo korin
T‘Imanueli, Oba won,
Gbe soke titi yo fi yi aye ka.

3 mf Gbe asia na soke,


Ko ma dan ni gbogbo ‘le
M‘ojo na yara de t‘yo ma fe lele:
cr Mu fo lat‘okun d‘okun,
Tit‘ aye yo gba Kristi;
Gbe soke titi yo fi yi aye ka.
Amin.

440 S.M.
A wa ti ri irawo re ni
iha ila-orun. Mat. 2:2.

1 f Irawo wo l‘eyi?
Wo b‘o ti dara to,
Amona awon keferi
S‘odo Oba ogo.

2 Wo awon amoye
Ti ila orun wa;
Won wa fi ori bale fun
Jesu Olubukun.

3 Imole ti Emi,
p Ma sai tan n‘ilu wa;
Fi ona han wa k‘a le lo,
Imanueli wa.

4 f Gbogbo irun-male,
Ati igba-male,
Ti a mbo n‘ile keferi,
K‘o yago fun Jesu.

5 mf Ki gbogbo abore
Ti mbe ni Afrika,
Je amoye li otito,
Ki won gb‘ebo Jesu.
6 Baba Eleda wa,
Ti O fi Jesu han
Awon keferi igbani;
Fi han fun wa pelu.
Amin.

441 6.6.6.6.8.8.
Yio si joba ni ile
Jakobu titi aiye. Lk. 1:33.

1 f Eyo Jesu joba


‘Nu omo eniyan
O da ara tubu
O so won d‘omnira:
K‘esu koju s‘Om‘Olorun,
Lai fota pe, ise Re nlo

2 mf Ise ti ododo
Oto, alafia
Fun rorun aye wa,
Yio tan ka kiri
Keferi, ju won o wole
Won o jeje gb‘ofin Re

3 f Agbara l‘owo Re
Fun abo eni Re,
Si ase giga Re;
L‘opo o kiyesi
Orun ayo ri ise Re
Ekusu rere gb‘ofin Re

4 Irugbin t‘orun yi
O fere d‘igi nla;
Abukun wukara
Ko le saitan kiri;
ff Tit‘ Olorun Omo tun wa
Ko le sailo, Amin! Amin!
Amin.

442 7s. 6s. D


Nigbati oko iyawo pe,
gbogbo nwon to gbe,
nwon si sun. Mat .25:5.

1 mf Oluwa y‘oti peto,


Ti ‘WO o tun pada;
Are fere mu wa tan,
Bi a ti nw‘ona Re;
Oluwa y‘oti peto
Ta o ma reti Re?
Opo ni ko gbagbo mo
Pe ‗Wo o tun pada.

2 Oluwa y‘o ti pe to
Ti 'Wo o kesi wa!
Ti awa ti nreti Re
Yio ri O l‘ayo
Ji, wundia ti o sun
Lo kede bibo Re
Ki gbogbo awon t‘o sun
Le mo pe O mbo wa

3 f Dide, tan fitila re


Gbe ewu mimo wo,
Mura lati pade Re
‗Tori On fere de
Oluwa y‘o ti pe to
Ti ‘Wo o tun pada?
Ma je ki are mu wa
Tit‘ ao fi ri O.
Amin.

443 14.8s
IWO ofi imo Re to mi li ona,
nigbakehin IWO O gba mi
sinu ogo. OD. 73:24.

1 Olorun mi b‘ojuwo mi
F‘iyanu ‘fe nla Re han mi:
Ma je ki ngbero fun ‘ra mi
‘Tori ‘Wo ni ngbero fun mi
Baba mi, to mi l‘aye yi
Je ki ‘gbala Re to fun mi.

2 Ma je ki mbu le O lowo,
‘Tori Wo li onipin mi:
S‘eyi ti ‘Wo ti pinnu re,
p Iba je ponju tab‘ ogo.

3 Oluwa tal‘ o ridi Re,


Iwo Olorun ologo?
Iwo l‘egbegberun ona,
Nibi ti nko ni ‘kansoso.

4 B‘orun ti ga ju aye 1o
Beni ‘ro Re ga ju t‘emi;
Ma dari mi k‘emi le lo
S‘ipa ona ododo Re.
Amin.
444 8.78.7.8.7.
imole lati mole si
awon Keferi.Lk. 2:32.

1 Wo! gbogbo ile okunkun,


Wo! okan mi, duro je:
Gbogbo ileri ni o nso
T‘ojo ayo t‘o logo;
Ojo ayo, ojo ayo,
K‘owuro re yara de!

2 mf Ki gbogbo ile agbaye


K‘alaigbede gbogbo ri
Isegun nla t‘o logo ni;
T‘ori oke Kalfari;
K‘ihinrere; k‘ihinrere
Tan lat‘ ilu de ilu.

3 Ijoba to wa l‘okunkun,
Jesu, tan ‘mole fun won
Lat‘ ila-orun de ‘WO re,
K‘imole le okunlo;
K‘irapada, k‘irapada.
Ti a gba l‘ofe b‘ori.

4 Ma tan lo ‗WO ihinrere,


Ma segun lo, ma duro,
K‘ijoba re ayeraye
Ma bi si, k‘o si ma re;
Olugbala, Olugbala,
Wa joba gbogbo aye.
Amin.

445 7.6.7.6.D.
Beli awa, eniyan Re ati
agutan papa Re yio mafi
ope fun O lailai, awa o ma
fi iyin Re han lati irandiran.
OD. 79:13.

1 f Oorun igbala wa,


Emi at‘iye wa,
Ilera at‘abo wa,
At‘ alafia wa;
Awa omo Re duro
Lati f‘iyin fun O
Fun ebun nla t‘O fun wa
Ninu Kristi Jesu.

2 Okan wa kun fun ope


Fun ‘toju ‘gbagbogbo
L‘ori awon omo Re
Ni gbogbo agbaye.
mf Awa mbe O jek‘awa
Le duro n‘nu‘fe Re;
F K‘imole wa le ma tan
Yi gbogbo aye ka.

3 ff Ogo f‘Olorun Baba,


At‘ Olorun Omo,
Pelu Olorun Emi,
Metalokan laelae;
Jo gba orin iyin wa
Ati adura wa
Fun ebun nla t‘O fun wa
Ninu Kristi Jesu.
Amin.

446 L.M.
E lo, e ma ko orile-ede
gbogbo. Mat. 28:19.

1 f L o wasu ihinrere Mi
Mu gbogbo aye gb‘ore Mi;
Eni t‘o gb‘oro Mi y‘o la,
Eni t‘o koo yio segbe.

2 Emi o f‘oye nla han yin,


E o f‘oro oto Mi han;
Ni gbogbo ise ti Mo se,
Ni gbogbo ise t‘e o se.

3 LO WO arun, lo j‘oku nde,


F‘oruko Mi l‘esu jade;
Ki woli Mi mase beru,
Bi Griki ati Ju kegan.

4 Ko gbogbo aye l‘ase Mi,


Mo wa lehin yin de opin;
Lowo Mi ni gbogbo ipa,
Mo le pa, mo si le gbala.

5 Imole si ran yi i ka,


Ogo nla l‘o fi lo s‘orun;
Won si mu de ile jijin,
Ihin igoke Olorun.
Amin.

447 O.t.H.C. 127. 8s. 7s.


Ibi okunkun aiye,
o kun fun ibugbe ika.
OD. 74:20.

1 mf E fi oju iyonu wo
Okun ile keferi:
Sa wo bi opolopo won
Ti njowere ‘nu ese,
p Okunkun bo, Okunkun bo,
Oju ile aye wa.

2 Imole eni okunkun,


Dide, mu ibukun wa
Imole fawon keferi,
Wa, pelu ‘mularada;
Ki gbogb‘Oba ki gbogb‘Oba
Wa sinu imole na.

3 Je k‘awon keferi ti mbo


Igi ati okuta
Wa lati Fi ori bale
Fun Olorun alaaye
Jek‘ogo Re, jek‘ogo Re,
Bo gbogbo ile aye

4 f IWO t‘a fi‘pa gbogbo fun,


Soro na! pa ase Re;
Jeki egbe Oniwasu
Tan ‘ruko Re ka kiri:
Wa pelu won, Wa pelu won
Oluwa titi d‘opin.
Amin.

448 6s. 4.
Awon Oba Seba ati ti Seba
yio mu ebun wa. OD. 72:10.

1 Lati erekusu
De ikangun okun,
K‘Oba juba Jesu.
Ki won mu ore wa
Ki Arab‘ le
Orin orun;
K‘ Afrika dapo
Gbe ‘yin Rega.

2 Om‘alade y‘o sin


Won o mu ore wa
Lati yin agbara
Imanuel Oba ;
Ile jinjin
Yio josin
Aye y‘o gba
Ase Re gbo
Amin.

449 8.7.8.7.
Oluwa wipe, wa nisisiyi
Bi nyin ba ri bi ododo, nwon
fun bi sno. Isa. 1:18.

1 f Elese wa sodo
Jesu Eni t‘o wa gba o la;
Eni t‘o gbe ara re wo
Lati ru irora re.

2 Olodumare ni Eni
T‘o fi emi Re fun o;
Orun at‘aye y‘o koja
Sugbon On wa titi lae

3 Ki ojo aye re to pin,


K‘iku to p‘oju re de,
P Yara, wa Olugbala re,
F K‘akoko na to koja.

4 Gbo b‘ohun Re ti nkepe o,


―Elese wa sodo Mi
Ko eru re na to Mi wa;
Gbagbo, reti, ma beru‘‘
Amin.

450 8.7.8.7.7.7.
Ma wi Oluwa, nitori iranse
Re ngbo. I Sam. 3:9.

1 Ma wi, ‘tori ‘ranse Re gbo,


Mo duro de oro Re;
Mo fe gb‘ohun iwosan Re;
Je k‘emi gbo, Oluwa,
Kristi, mo t‘eti sile
S‘ohun t‘O fe wi fun mi.

2 Ma wi, pe mi, Oluwa mi,


Je ki nle mo ohun Re:
Ma wi, ki nyara te le O,
Kin sun mo O girigiri
Nibit‘O nto agbo Re;
Labe ibi itura.

3 Ma wi, yala l‘ohun jeje


Ma je k‘emi lo laigbo;
Ma wi, Oluwa, Iwo mo
Gbogbo ero okan mi,
IWO m‘ohun ti mo fe
So mi di eni ‘bukun.

4 Ma wi, je ki emi mura


Bi mo ba ti gb‘ohun Re;
Pelu ‘gboran ati ayo,
Ni ki nfi tel‘oro Re
Kristi, mo teti sile
Mawi, Oluwa mawi
Amin.

451 6.6.6.6.D.
Emi o si pelu enu re,
Emi o si ko o li eyiti
iwo o wi. Eks. 4:12.

1 mf Tan ‘mole Re si wa
L‘oni yi, Oluwa
Fi ara Re han wa
N‘nu oro mimo Re:
Jo m‘okan wa gbona,
Ka ma wo oju Re
K‘awon ‘mode le ko
Iyanu ore Re

2 mp Mi si wa, Oluwa
Ina emi mimo;
cr Ka le fi okan kan
Gbe oruko Re ga;
JO fi eti igbo,
At‘okan ironu,
Fun awon ti a nko
L‘ohun nla t‘O ti se.

3 mf Ba ni so Oluwa,
Oro Re ti a nso;
Jeki eko wa je
Gegebi oro Re;
K‘awon agutan Re
Le ma mo ohun Re;
Ibit‘Onto won si
cr Ki won si le ma yo.

4 mf Gbe ‘nu wa Oluwa,


K‘ife Re je tiwa;
Iwo nikan la o fi
Ipa wa gbogbo sin;
K‘iwa wa je eko,
Fun awon omo Re,
di Ko si ma kede Re
Ninu gbogbo okan.
Amin.

452 7.7.9.7.7.10. & Ref.


Kiyesii, Igboran sanju ebo lo.
I Sam. 15:22.

1 mp B‘Olorun Oba orun .


Ti ma nsoro n‘igba ni;
O tun ba wa soro be loni
Arakunrin oto ni
Ohun t‘O ba wi fun o;
Ohun kan l‘aigbodo-mase:
Gboran.
mp Sa gboran, sa gborin
Eyi ni ‘fe Re.
‘Gbat‘ O ba ranse si o,
Ohun kan ni ki o se
Sa gboran, sa gbornn

2 cr Bi o ba je t‘Oluwa
Onilati gbo tire,
Kos‘onu ‘hinrere miran mo
Ma sa ase Re ti
Ma si se lo oro Re,
‗Gbat‘Olugbala ba nsoro, sa
Gbo.

3 mf Bi o ba fe ni ipin
Ni ‘lu daradara ni
Leyin aye wa buburu yi;
Bi o ko tile m‘ona,
Krist‘ y‘o wipe, ―tele Mi‖
Igbagbo yo si wipe, "sa gboran‖
Amin

453 8.8.9.8. & Ref.


Oro Re ni fitila fun ese mi
ati imole si ipa ona mi.
OD. 119:105.

1 f Bibeli iwe iyanu


Ti o nf‘ona han araye,
Fitila li ntan si ona wa,
Lat‘aye yi Il'oke orun.
ff Tan ‘wo ‘mole at‘oke wa.
Tan si okunkun ayeyi,.
Tan ninu oru ‘yemeji
Titi oro titun yo fi de.

2 mp Bibeli, ofin Oluwa


Ti okun fun ore-ofe;
Ni pipamo re, ere nla mbe,
N‘nu re la ri 'ye ailopin.

3 Bibeli, iwe imole,


Ti o tan lati oke wa;
Iranwo ti o l‘ogo julo,
Da ‗na ife si okan wa.
Amin

454 6.4.6.4.D.
Jesu wifun won pe,
e wa jeun owuro. Jn. 21:12.

1 mp B ‘onje lye fun mi


Oluwa mi,
B‘O ti bu akara
Leba odo;
Ninu iwe mimo
Ni mo nwa O,
Okan mi nfa si O.
Oro iye!

2 mf ‘Wo li onje iye,


Oluwa mi,
Otito oro Re
Ni yo gba mi,
cr Jeki nje ninu Re,
Ki mba O gbe;
Jeki nfe oto Re
Ife ni O!

3 p Ran Emi Re simi,


Oluwa mi,
Ki O si la ‘ju mi,
cr Ki nle riran,
mf Otito oro Re
Fi han fun mi;
cr Ki nri O, Oluwa
N‘nu iwe Re
Amin.

445 8.8.8.D.
Ki iwo ki o si ma fi won
ko awon omo re nigbati
iwo bajoko ninu ile re. Deut. 6:7.
1 mf Nigba mo joko n‘ile mi,
Ki iwe Re se ‘keji mi;
cr Ki nma f‘ayo ka oro Re,
Ki nsi ma rohun ife Re
Ki nwadi oro mimo na
Titi yoo fi je temi.

2 mf Jek‘oro ore-ofe Re
Je kiki oro enu mi!
Be l‘Oluwa yo ba mi rin,
Y‘o tikare ba mi soro
Be l‘okan mi yo m‘oju Re,
Y‘o si kun fun ‘fe ailopin.

3 mf Nigbati mo ba dubule,
Jeki oro ilana na
Ki o fi aya mi bale,
Ki nsimi laya Baba mi,
Ki nsun fonfon ki nsi l‘ayo
Ki nsi r‘iran ayeraye.

4 f Ki nyin Oluwa ‘gba mba ji,


Ki nkede Re l‘ojo gbogbo,
Ki nje k‘oro or‘-ofe Re
Kun okan ati ahon mi;
cr K‘ife Re gba emi mi kan,
Si ka mi mo ijo t‘oke.
Amin.

456 8.,7.8.7.
Ibukun nifun awon ti ngbo
oro Olorun ti nwon si
ona mo. Lk. 11:28.

1 mf Bukun wakati na ti to
Jesu, ‘gba t‘a sunmo O
Lati gbo oro ‘yebiye
Ti nti enu Re jade!

2 Pelu wa loni bukun wa,


Ka ma j‘olugbo lasan;
Te oto Re mo wa l‘aya,
Ti mbe n‘nu oro iye.

3 f Wo wab‘a tin wa igbala,


Ti a joko l‘ese Re.
A nreti ni iparoro
Lati gb‘ohun didun Re.
4 mf La wa n‘iye, k‘O si to wa
L‘alafia l‘ona orun;
F‘atupa oto saju wa,
Ki a ma ba sina lo.

5 Se wa l‘eni tutu, pele,


K‘a ma figboya s‘oto
cr L‘okun lo, ka ma ba kose,
Ko s‘ewu ninu ‘mole.

6 mf F‘imole, ife, agbara


Fun oro Re lat‘oke
Ko ma sise b‘iwukara
Ni inu wa titi lo.

7 f Ran wa lowo, ka le jeri


Si otito t‘a dimu;
Ka si je k‘awon elomi
To adun oto na wo.
Amin.

457 7.7.7.7
Emi ti fe ofin Re to!
OD. 119:97

1 mf Bibeli mimo t‘orun,


Owon itura temi!
‘Wo ti nwi bi mo ti ri
‘Wo li imo bi mo ti wa.

2 p ‘Wo nko mi bi mo sina,


cr ‘Wo nfi ‘fe Oluwa han;
‘Wo l‘O si nto ese mi,
mf ‘Wo l‘O ndare, at‘ebi.

3 f ‘Wo ni nma tu wa ninu


Ninu wahala aye;
cr ‘Wo nko ni nipa ‘gbagbo
Pe, a le segun iku.

4 f ‘Wo l‘O nso t‘ayo ti mbo


At‘iparun elese;
Bibeli mimo t‘orun,
Owon isura temi.
Amin.

458 6.6.6.6.
Oro Re ni fitila fun ese
mi ati imolesi ipa ona mi.
OD. 119:105
1 mf Jesu oro Re ye,
O si nto ‘sise wa,
Eni t‘o ba gba gbo,
Y‘o l‘ayo on ‘mole.

2 p Nigb‘ota sunmo wa,


Oro Re l‘odi wa;
Oro itunu ni,
Iko igbala ni.

3 p B‘igbi at‘okunkun
Tile bo wa mole;
cr ‘Mole Re yo to wa,
Y‘o si dabobo wa.

4 mf Tani le so ayo,
To le ka isura
Ti oro Re nfi fun
Okan onirele

5 Oro anu o nfi


‘Lera fun alaye;
Oro iye o nfi
p Itunu feni nku.

6 mf Awa iba le mo
Eko ti O nkoni;
Ki a ba le fe O.
K‘a si le sunmo O.
Amin.

459 7.6.7.6.D.
Oro Re ni fitila fun ese mi
ati imole si ipa ona mi.
OD. 119:105.

1F IWO Oro Olorun,


Ogbon at‘oke wa;
Oto ti ki yipada,
Imole aye wa:
cr Awa nyin O fun 'mole,
T‘inu iwe mimo;
Fitila fun ese wa
Ti ntan titi aye.

2 mf Oluwa l‘O f‘ebun yi


Fun Ijo Re l‘aye,
A ngbe ‘mole na soke
Lati tan y‘aye ka,
Apoti wura n‘ise,
O kun fun otito,
Aworun Kristi si ni,
Oro iye, loto

3 f O nfe lele b‘asia


T'a ta loju ogun;
O ton b'ina alore,
Si okunkun aye;
Amonu eniyan ni,
p Ni wahala gbogbo,
Nin‘arin omi aye,
cr O nto wa sodo Krist‘.

4 f Olugbala se‘jo Re
Ni fitila wura;
Lati tan Imole Re
Bi aye igbani;
KO awon ti o sako,
Lati lo‘mole yi
Tit‘okun aye y‘o pin,
Ti won o r‘oju Re.
Amin.

460 C.M.
Oluwa ise Re ti PO to!
OD. 104:24.

1 mf Iwe kan wa ti kika re


Ko soro fun eeyan;
Ogbon ti awon to ka nfe
Ni Okan ti o mo.

2 mf Ise gbogbo t‘Olorun se


L‘oke nile, n‘nu wa;
A ko won sinu iwe na
Lati f‘Olorun han.

3 Awosanma t‘o ga julo,


Dabi ‘fe Olorun
Labe eyi ti gbogb‘eda
Mbe li alafia.

4 Okun, lati ayeraye,


Nfi egbarun ahon
Kede oko to ga julo
Pelu awon angeli.

5 mf Iwo ti O jeki nle ri


Ohun to dara yi;
Fun mi l‘okan lati wa O,
K‘a ri O nibi gbogbo.
Amin.
461 CM
Ilana re li o ti nse orin mi
ni ile atipo mi. OD. 119:54.

1 f Baba orun nin‘ oro Re


L‘ogo ailopin ntan;
Titi lae la ma yin O
Fun Bibeli Mimo.

2 mp Opo ‘tunu wa ninu re


Fun okan alare;
Gbogbo okan ti ongbe ngbe
Nri omi iye mu.

3 To wa s‘orun ka le n‘ipin
Nibi t‘ayo gbe wa:
Mu wa de odo Olorun,
Ka simi n‘nu Re lae.

4 mf Iba le ma je ayo mi,


Lati ma ka titi;
cr Ki nma ri ogbon titun ko
N‘nu re lojojumo.

5 mf Oluwa Oluko orun,


Mase jina si mi:
Ko mi lati fe oro Re .
Ki nri Jesu nibe.
Amin.

462 C.M
Oro mi ki yio pada
sodo Mi lofo. Isa. 55:11.

1 mf Olorun, a SO Oro Re
Bi ‘rugbin lor‘ ile;
Je k‘iri orun se sile
Ko mu ipa re wa.

2 K‘ota Kristi on Eniyan


Ma se sa 'rugbin na
K‘o f idi, mule l‘okan wa,
K‘o dagba ni ife

3 cr Ma je ki aniyan aye
Bi irugbin yi je;
K‘o si so eso ororun,
F‘alafia at‘ayo!

4 Olorun, jo, sokale wa,


F‘agbara f‘oro Re;
Ki gbogbo okan to gba O
Le mo igbala Re.
Amin.

463 6.5.6.5.
Ma wi, Oluwa, nitori iranse
Re ngbo, I Sam. 3:9.

1 mp Bami soro, Jesu,


Mo nduro de O;
KO mi ba ti nduro
Lati gbohun Re.

2 Ba mi so, Oluwa,
Ni wakati yi;
Jeki nri oju Re,
At‘agbara Re.

3 Oro enu Jesu,


Oro iye ni;
Onje atorunwa,
Ma fi b‘okan mi.

4 mf Fi kun mi, Oluwa


Ekun Emi Re;
Bi iri lat‘oke,
Jek‘o ba le mi

5 mp Mo f'ara mi fun O,
Ki nle je Tire;
Emi, okan, ara,
Fi mi se Tire.

6 cr Ma wi Oluwa, wi,
Iranse Re ngbo;
Emi nteti lele
Lati gbo 'ro Re

7 Fun mi ni imo si,


Ki nmo ife Re;
Ki gbogbo ife Re
Le se ninu mu.

8 Bi igi ti a gbin
Si eba odo;
Be ni ki aye mi
Ma mu eso wa.
Amin.

464 8.8.8.D.
Gbogbo iwe mimo ti o
ni imisi Olorun
li o si ni ere fun eko.
II Tim. 3:16.

1 mp Nipa imisi Re, l‘awon


Mimo igbani k‘oro Re,
B‘o ti wa latetekose
Be lo wa titi d‘isiyi;
Iye ti mbe n‘nu oro na
JO, mi si inu Okan wa.

2 B‘a ti nka Oro mimo na


Pelu adura at‘ife,
Ran Emi Re lat‘oke wa
Ki o le so okan wa ji;
Le gbogbo okunkun wa lo,
F‘imole Or‘-ofe to wa.

3 p Nigbati a ba si sako,
Ti a ko Olorun sile,
JO, fi oye ese ye wa;
Ba wa wi, si mu wa pada;
Mu wa banuje f‘ese wa,
Si foro Re tu wa ninu.

4 cr Mu wa k‘eko ore ofe


Lati inu Oro iye;
Ko wa ni gbogbo ona Re,
Mu wa mo pipe ife Re
Mu gbogbo Ipinnu Re se,
So wa di okunrin pipe

5 mf Pese wa fun ise rere,


Ohun-elo ta ya soto,
K‘a je iranwo f‘elomi
Ni ipokipo ti nwon wa,
Lati to won, lati ko won,
L‘ ona iye ainipekun.
Amin.

465 L.M.
Oro re dunju oyinlo li enu mi.
OD. 119:103.

1 mf Didun l‘Oro Re je fun mi,


Oluwa, mo ti fe won to;
Imole re ntan l‘ona mi,
Ogo re ntan lat‘oke wa.

2 f Mo ri ayo nin‘Oro na,


Ijura iyebiye ni;
Lati mo ijinle ‘fe Re,
Lati ma w‘ogo ite Re

3 cr Ogbon eniyan ko le ko,


Oye eniyan ko le mo;
Nipa imisi Re nikan
L‘a fi ko iwe mimo na.

4 mp Iwe iyanu n‘Iwo gbe


Le awa eda Re lowo;
Awon eni-mimo ‘gbani,
Nipa Emi, won kowe na.

5 f Omi iye ni f‘okan wa,


Eko re nmu inu wa dun;
O nso ‘gbagbo at‘ife ji,
O nmu ki ipe wa daju.

6 mf Iwo otito at‘ife


Ti O nfona iye han wa,
F‘ore-ofe fun gbogbo wa
K‘a je pipe niwaju Re.
Amin

466 7.6.7.6.D. & Ref.


Ki o si gbo gbogbo eyiti
Oluwa Olorun wa yio wi. Deut. 5:27.

1 p Bami soro Oluwa


Soro l‘ohun jeje
Ki ngbo ohun ife Re:
―Emi wa pelu re‖
Lu mi ni ookan aya
Ki nyara gbohun Re,
F‘orin ‘yin kun okan mi
Ki nl‘ayo ninu Re
pp Wi fun mi l‘ohun jeje
Ohun ife didun,
Pe ―un o ju asegun lo,
Un o bo patapata
‘Jojumo ki nle ma gbo
Ohun Emi didun
Soro na fun mi loni;
―Emi wa pelu re‖
2 mp Wa b‘awon ‘mo Re soro
To won s‘ona mimo,
Fi ayo kun okan won;
Fi adura ko won;
Ki won fara won rubo,
Ki won faye won ji
K‘ijoba Re yarade,
K‘oju wa le ri O.

3 mf Soro bi ti igbani,
Fi ife Re han wa,
Ki nmo gbogbo ise mi,
Ki nmu ase Re se;
To mi ki ngb‘ogo Re ga,
Ki nfi iyin Re han,
Ki nma fayo jise Re,
Ki ngbe O ga titi.
Amin

467 C.M
La mi li oju ki emi ki o le ma
Wo ohun iyanu wonni lati inu ofin re
OD 119:18

1 mf Baba eda, n‘nu Eni ti


A wa, a nrin, a nmi;
Ran ‗tansan orun sokale,
Wa mu wa laraya

2 p ‗Gbat‘ a nwa O n‘nu oro Re,


Pelu iwariri
La wa l‘oju, si je k‘ a ri
Iyanu ofin Re

3 mp Jeki Okunkun wa le ri
‗Mole ti ntan sansan;
Ran Emi ‗fihan sokale,
Fun wa l‘eti ‗gboran

4 cr Mu ore Re ti a gbogbo
Koja niwaju wa;
Jek‘ a r‘oju Re n‘nu Jesu,
K‘a ko ohun aye.
Amin.

468 8.8.8.D
Oro re ni fitila fun ese mi,
Ati imole si ipa ona mi. OD 119:105
1 mf Wa, Iwo Woli Oluwa,
Ogbofo nla ti Olorun,
Se ‗tumo oro Re fun wa,
Iwo nikan l‘o le ko wa;
Jowo, mas‘aif‘ara Re han,
Si iwe Re lasipaya

2 mp Kristi, f‘oro Woli han wa,


Ti won ti so ni ipa Re;
Olu oro iwe mimo,
Nipa Re l‘a ko gbogbo won,
Sibe ao le ri O nibe,
Bi EmiRe ko si fun wa

3 mf Jesu, mu ‗boju wa kuro


Ati airiran okan wa;
Fi iyanu ife Re han,
Jeki a mo O b‘o ti ye
A te ‗ti on okan wa ba
Ma wa, n‘tori ‗ranse Re ngbo.
Amin.
469 C.M.
Ifihan Oro Re fun ni ni imole;
o si fi oye fun awon ope.
OD 119:130.

1 mp Emi nmi s‘ori oro na,


O nf‘oto Re han wa;
Ilana oun ileri Re
Ntan imole mimo

2 f Ogo kan yi iwe na ka,


O mole bi orun:
Imole ti ko nipekun
L‘o nikan fi fun ‗ni

3 mf Eni t‘o f‘oro yi fun wa,


O mbe sibesibe;
Oto Re yo s‘oril‘-ede,
O yo, ki o wo mo

4 ff Jek‘a f‘ope aiti fun O


Fun iru mole yi,
T‘O mu ki imole orun
Tan s‘okunkun aye

5 f Okan mi nyo lati to ‗pa


Es‘ eni ti mo fe,
Titi un o fi ri ogo Re
L‘aye didan loke.
Amin

470 11.10.11.10. & Ref


E ma wa inu iwe mimo
Jn. 5:39

1 f Di Bibeli mu b‘ohun miran kuna,


Ma so ilana Re to s‘owo nu;
Ihin ayo Re njo okan ti ntogbe
Iye si ni ‗leri re je fun o
Ff Di Bibeli mu! Di Bebeli mu!
Oluto, amoona lo je fun wa

2 mf Di Bibeli mu, ‗sura ‗yebiye ni;


O nf‘iye anipekun f‘araye;
Ko si ida na to le won iye re;
Wa ibukun re nigba to le ri

3 f ‗Mole ni fun gbogbo awon asako,


Amona fun odo t‘iba subu;
‗Reti f‘elese t‘aye re ti daru,
Opa f‘ogbo iwe to dara ju.
Amin.

471 8.8.8.D.
Iwe mimo ti o le mu O di
Ologbon si igbala. II Tim. 3:15.

1 mf Mo feran iwe oro Re.


O f‘imole at‘ayo fun
Okan okun on ‘binuje!
Oro Re t‘ona mi wiwo;
Eru Re ko jeki nsirin.
‘Leri Re m‘okan mi simi

2 mf Eru Re ji mi n‘ntfgbe mi,


O so bit‘ewu mi gbe wa;
Sugbpn Oluwa, oro Re
di L‘o so okan mi di mimo,
L‘o te ori ese mi ba
L‘o si m‘ere nla wa l‘ofe.

3 mp Tani mo ebi okan re?


Dari sise koko ji mi,
di Gba mi low‘ese agidi,
K‘O si gba iyin ‘rele mi,
Fun aika ‘we ore-ofe
At‘eri ise Re lasan.
Amin.
472 C.M
Omokunrin tujuka, a dari
ese re ji o. Mat. 9:2.

1 f Jesu mi, mu mi gb‘ohun Re,


S‘oro alafia;
Gbogbo ipa mi y‘o dalu
Lati yin ore Re.

2 p Fi iyonu pe mi l‘omo,
K‘O si dariji mi:
Ohun na yio dunmo mi,
B‘iro orin orun.

3 f Ibikibi t‘O to mi si,


L‘emi o f‘ayo lo
Tayotayo l‘emi o si
Dapo m‘awon oku.

4 f ‘Gba eru ebi ba koja,


Eru mi ko si mo;
Owo t‘o fun ‘dariji ka,
Y‘O pin ade iye.
Amin.

473 C.M.
Nipa ewo li odomokunrin yio
fi mu ona re mo? Nipa ikiyesi
gege bi oro re. OD. 119:9.

1 mf Bawo ni awon ewe wa,


Y‘otima soro won?
Bikose ―nipa‘kiyesi,
Gege bi oro Re.‖

2 ‘Gba oro na wo‘nu okan,


A tan imole ka;
Oro na ko ope l‘ogbon,
At‘ imo Olorun.

3 f Orun ni, imole wa ni,


Amona wa l‘osan;
Fitila ti nfonahan wa,
Ninu ewu oru.

4 Oro Re oto ni titi,


Mimo ni gbogbo re:
Amona wa l‘ojo ewe.
Opa l‘ojo ogbo.
Amin.
474 C.M.
Mo ri Oro Re mo si je won.
Jer. 15:16.

1 mf Bibel‘ iwe ayeraye!


Tani ler‘idi re?
Tani le so idide re?
Tani le m‘opin re?

2 f Asiri Olodumare;
Iko Oba orun;
ff Ida t‘o pa oro iku,
Aworan Olorun.

3 mf Okan ni O larin opo


Iwe aye ‘gbani,
Iwo l‘o s‘ona igbala
Di mimo f‘araye.

4 mf Isura ti Metalokan,
Ff Oba nla t ‘ O gun wa;
Jo, tumo ara re fun mi,
Ki ‘m‘ye siyemeji.

5 Ki‘m‘ si O pelu adura,


Ki‘m‘ k‘eko ninu re;
Iwo iwe ayeraye
F‘ife Jesu han mi.
Amin

475 8.8.9.8.8.8.8.4.
La mi li oju ki emi ki o le
ma wo ohun iyanu wonni
lati inu ofin Re.
OD. 119:18.

1 mp La mi l‘oju ki mba le ri
Oro otito Re fun mi;
Fi ijinle ife Re han mi
Ti y‘o SO mi di omnira;
p Ni ‘dakeje ni mo nduro;
Mo mura lati se ‘fe Re,
La mi l‘oju, mu ‘mole wa
Emi Orun.

2 mf Si mi l‘eti, ki mba le gbo


Ohun otito Re fun mi;
Je ki iro opo ohun Re
Tu gbogbo etan esu ka;
p Ni ‘dakeje ni mo nduro,
Mo mura lati se ‘fe Re
Si mi l‘eti, mu ‘mole wa
Emi Orun.

3 mf La mi l‘ohun ki mba le so
Oro otito Re yika;
RO mi l‘okan, mura mi sile
Ki nle to adun ‘fe Re wo.
p Ni'dakeje ni mo nduro,
Mo mura lati se 'fe Re,
Ro mi l'okan, mu 'mole wa
Emi Orun.

4 mp Si mi n‘iye, ki mba le ka
Ti ife Re nin‘ oro Re;
Kini y‘o tun ma deruba mi
‗Gbati ‗mole Re ba nto mi;
P Ni ‗dakeje ni mo nduro
Mo mure lati se‘fe Re
Si mi ni ‗ye, mu mole wa,
Emi Orun

5 La ‗na sile k‘emi le mu


Ebun ofe wa f‘Oba mi;
N‘nu ife, oro Re y‘o dun ju
Orin t‘awon angeli nko;
P Ni ‗dakeje ni mo nduro,
Mo mura lati r‘ife Re,
La ‗na sile, mu ‗mole wa,
Emi Orun
Amin.

476 C.M.
Okan wa ko ha gbina ninu wa,
nigbati O mba wa soro
li ona Lk. 24:32.

1 mp Ba wa soro, fara han wa,


Lona ajo aye;
B'okan wa soro, jek‘a mo
Igbona ife Re

2 O mba wa soro, a gbagbe


‗Gba lala at‘apon;
Lala je‘simi, ‘rora dun,
B‘Olorun wa nihin.

3 mf Olorun mi, jo ma gbe'hin,


Jek‘okan mi mayo;
Okan mi y‘o gba ase Re,
Y‘o si je ipe Re

4 cr 'Wo pe mi ki nwa oju Re


On ‘na ni mo fe wa;
Mo fe teti s‘or‘ ofe Re,
Ki nsi gbo ohun Re.

5 f Je ki nf‘eyi se ise mi,


Titi un o r‘ogo Re;
Ti uno bo s‘ayo Baba mi,
Ninu alafia.
Amin.

477 7.7.7.7.D.
Eyi ni ayanfe omo mi,
Eni ti inu mi dun si gidigidi.
Mat. 3:17.

1 mp Jesu ti o gba mi la
WO ‘nu odo Jordani;
O jade kuro n‘nu re,
A si m‘O‘l‘Om‘Olorun,
Nipa ohun ‘fe Baba,
At‘iwa le adaba;
Jesu Oluto t'emi
Bi Re mo fe ‘tebomi.

2 pp Nin‘ogba ibanuje
Bo okan Re bi omi;
Ni Kalfari l‘origi
A! ni Jesu ku fun mi,
A kan mi po pelu Re;
‘Reti mi ni pe O ku;
Mo ni ‘po mi lese Re,
Mo njiya nitori Re.

3 p N‘nu ‘boji titun lo sun,


O mu eru Re kuro,
O la ‘kuta re koja,
O l‘ogo titi laelae;
Mo fe ka sin mi mo Krist‘
Nin‘ ase ta bere yi,
Bi mo si ti nyo s‘oke,
Ki nwa l‘otun s‘Olorun.
Amin.

478 10.10.10.10. & Ref.


Kiyesi, iru ife ti Baba ti fun wa,
Pe ki a le ma pe wa ni omo Olorun
I Jn3:1

1 f Mo yo pupo pe Baba wa orun


Bot‘ife Re ninu ‘we t‘O fun mi,
Mo r‘ohun ‘yanu ninu Bibeli,
Eyi s‘OWON ju pe, Jesu fe mi.
ff Mo yo pupo pe Jesu fe mi,
JESU fe mi, Jesu fe mi,
Mo yo pupo pe Jesu fe mi,
Jesu feran‘emi.

2 mp ‘Gba mo gbagbe Re, ti emi sa lo,


O fe mi sibe, O wa mi kiri;
Mo yara pada s‘apa anu Re,
‘Gbati mo ranti pe Jesu fe mi.

3 f Bi o se orin kan l‘emi le ko,


‘Gba mo r‘Oba nla ninu ewa Re;
Eyi ni yo ma j‘orin mi titi,
A! iyanu ni pe, Jesu fe mi.

4p Jesu fe mi, mo si mo pe mo f‘E,


Ife lo mu wa r‘okan mi pada
Ife lo m‘U k‘o ku l‘ori igi
O da mi loju pe, Jesu fe mi.

5 mp Emi-o ti se dahun b‘a bi mi


Ohun ti ogo Oluwa mi je?
Emi mimo njeri nin‘okan mi,
Ni igba gbogbo pe, Jesu fe mi.

6 f Ni‘gbekele yi ni mo r‘isimi,
N‘igbekele Krist‘ mo d‘alabukun,
Satan damu sa kuro l‘okan mi,
Nigba mo so fun pe, Jesu fe mi.
Amin.

479 C.M.
Gbogbo wa ta ti baptisi sinu
Kristi Jesu a ti baptisi wa sinu
iku Re. Rom. 6:3.

1 mf Jesu, Iwo l‘a gb‘ohun si,


Mi Emi Mimo Re
Si awon eniyan wonyi
Baptis‘ won s‘iku Re

2 mp K‘O fi agbara Re fun won.


Fun won l‘okan titun;
Ko ‘ruko Re si aya won,
Fi emi Re kun won.

3 mf Jeki won ja bi ajagun


L‘abe opagun Re;
Mu won f‘otito d‘amure,
Ki won rin l‘Ona Re.

4 mp Oluwa, gbin wa s‘iku Re,


K‘ajogun iye Re;
L‘aye, ka ru agbelebu,
K‘a ni ade Orun.
Amin.

480 L.M.
Baptist won li oruko Baba
ati ni ti Omo ati ni ti
Emi mimo. Mat. 28:19.

1 mf Wa Emi Mimo sokale


Oni baptisi okan wa;
M‘edidi majemu Re wa,
K‘O si se eri omi yi.

2 ff Tu agbara nla Re jade,


K‘O si won eje etutu;
Ki Baba, Omo at‘Emi,
S‘awon yi d‘omo Olorun.
Amin

481 S.M.
Dide, ki a si baptisi re.
Ise A. 22:15.

1 f Duro, om‘ogun Krist‘,


F‘enu re SO f‘aye,
Si jeje pe, ―ofol‘aye‖
Nitori Jesu re.

2 mf Dide, ka baptis‘ re,


Ko we esere nu,
Wa b‘Olorun da majemu
Jewo igbagbo re

3 cr ‘Wo ki se t‘ara re
Bikose ti Kristi;
A ko oruko re po mo
T‘awon mimo ‘gbani.

4 mf Ni‘hamora Jesu
Kojuja si esu;
Bo ti wu k‘ogun na le to
Awa ni yo segun.

5 f Ade didara ni,


Orin na, didun ni;
‘Gba ta ba ko ikogun JO
S‘ese Olugbala.
Amin.

482 8.7.8.7.
Nitorina e LO, e ma ko
orile-ede gbogbo,
ki e si ma baptisi won ni
oruko Baba, ati ni ti Omo ati
ni ti Emi Mimo Mat. 28:19.

1 mf E ni ‘rele t‘o nwa ‘gbulu


Nip‘eje Od‘-agutan.
E gbo ohun isipaya,
Erin ‘na ti Jesu rin.

2 mf Gbo Olugbala t‘O npe yin,


F‘eti s‘ohun Re orun,
di Ma beru ibi t‘o le de,
Nigbat‘ eyan onu Re

3 mf Jesu wipe, ―Se ‘tebomi


Fun awon t‘o gba Mi gbo;‘‘
A te On papa bo ‘mi ri,
Ninu odo Jordani.

4 mf Eto ipase Re nihin,


To lehin laiduro pe;
E fi ayo gba ase Re,
Wo! Olori yin saju.
Amin.

483 C.M.
Eniti on tikarare, fi ara
re ru ese wa de ori igi.
1 Pet. 2:24.

1 mp Oluwa, nje ‘dariji Re


Yio gb‘eni bi emi?
Nje, O gbe ese mi kuro
O ferin bukun mi?

2 Nje fun mi l‘O r‘agbelebu


Lai nani egan Re?
Jesu, o ha to ki ntiju
Biba O lo s‘odo?

3 O se ‘ra Re l‘apere nla


Li odo Jordani?
Igberaga mi yio ha ko
Lati s‘ohun t‘O se?

4 Jesu, itara ife Re


Mba ilora mi wi;
Ese mi nisiyi si nrin
Li ona didun Re.
Amin.

484 C.M.
Bi a ti sin nyin PO pelu re
nipa baptismu, nipase eyiti a
si tiji nyin dide pelu re nipa
igbagbo ti ise ife Olorun. Kol. 2:12.

1 mf A Baptis‘ wa sinu iku,


Nipa itebo ‘mi;
A sin wa ‘nu ‘boji Jesu,
A sin wa pelu Re

2 Aba Krist‘ ku k‘abaye se.


K‘a le ji pelu Re,
K‘ale jere ebun titun
T‘y‘o mu wa ye f‘oke.

3 p Emi, fi ara Re fun wa;


K‘oro wa ko le je
Ireti Oluwa l‘oke
At‘ifarahan Krist‘.

4 Fun igbagbo wa li ogo,


Ayo ati ade,
Lat‘ aye k‘a le wa l‘oke
K‘a joko pelu Krist‘.
Amin.

485 L.M.
Nje a si n baptismu sin wa
PO pelu re sinu iku. Rom. 6:4.

1 mp Ako ha gb‘oro wuwo ni,


P‘a sin wa pelu Oluwa?
P‘a te wa ri sinu ‘ku Re,
A si bo ara osi ‗le.

2 f Okan wa gba emi t‘orun,


A gbe kuro ninu iku;
Beni Krist‘ Jinde n‘iboji,
O si mb'Oloorun gbe l‘oke.

3 mp K‘a ma jek'esu tun joba


Ninu ara iku wa mo,
Gbogbo ese ti a ti nda,
Ki yio j‘oba l‘ori wa mo.
Amin.

486 L.M.
Enikeni ti o ba gbaagbo ki yio
segbe, fugbon yio ni iye ti
ko nipekun. Jn. 3:16.

1 mf Oluwa orun at‘aye!


Jesu, Omo ninu ara!
Emi Mimo fun ‘toju wa!
Egbo, ki E si gb‘eje wa.

2 mp A gba O, Jesu ti a pa,


A gba ‘WO t‘O r‘oke orun;
Pelu Re a ti ku s‘ese,
Okan wa si nfe ba O ji.

3 A gba ihinrere Re gbo,


A nlo, owo Re yio to wa;
L‘odo Jordani a nw‘ona
T‘awon Tire gba d‘odo Re

4 p Nipa ‘tebomi ami nla


Awa fi ara wa fun O
F‘edidi te majemu na,
K‘O gba wa la fun Tire.
Amin.

487 L.M.
Eyiyi li ayanfe Omo mi,
eniti inu mi dun si gidigidi;
e ma gbo tire.
Mat. 17:5.

1 mf Gbo ohun t‘o dun lat‘oke


Si Jesu l'odo Jordani,
Eri fun gbogbo araye
―Eyi l‘ayanfe Omo Mi.‖

2 Alailese, Eni pipe,


Sugbon nitorit‘ a pase
Iwenumo ninu odo,
O f‘ara Re se apere

3 Omo okan aya Baba,


Igbala fun gbogbo eda,
Orisun iye elese.
Jordani t‘oke Kalfari.

4 Wa, tele Olugbala re,


Ninu ase ilo s‘odo,
Apere iba Jesu ku,
Ati ajinde pelu Re.

5 f Wa, ma tan idi asiri


T'o wu Oluwa lati bo,
F‘igboran saju; nikehin
Ere re y‘o fi ara han.
Amin.

488 8.7.8.7.4.7.
Eni ti o ba gbagbo, ti a ba si
baptisi re yio la; sugbon eniti
ko ba gbagbo yio jebi.
Mk. 16:16.

1 mf Wo, awon t‘o wo 'so ala


Won duro leti odo,
Won k‘eyin s'aye at‘esu
Won ntele Atebomi;
F Won si nreti.
Lati se ase Jesu.

2 mf Wo bi won ti duro l‘eru,


Sugbon pelu ireti,
Won mo pe Olugbala won
L‘Opase odo lilo.
F Jordan‘tutu,
Sugbon igbagbo gbona.

3 mf Si wo awon arakunrin
Egbon won ninu Jesu,
Wo bi won ti na 'wo ife
Won sa ti dabi won ri,
Nisisiyi,
Won ny‘ayo idariji.

4 f Lo tele Olugbala yin;


E f‘oju igbagbo ri;
A! orun si, Emi Baba
Sinke lat‘ oke wipe,
ff ―Awon wonyi
Ni ayanle omo Mi.‖
Amin.

489 7.ft.7.6.D.
On wasi baptisimu ironunpiwada
fun imukuro ese. Lk3:3.

1 mf Ohun ti ndun l‘aginju,


Ohun alore ni,
Gbo b‘o ti ndun rara pe,
―E ronupiwada‖
Ohun na ko ha dun to?
Ipe na ko kan O?,
Kil‘ o se, arakunrin,
Ti o ko fi mira?

2 f ―Ijoba ku si dede‖
Ijoba Olorun,
Awon t'o ti fo ‗so won
Nikan ni yio gunwa
Ese t‘o ko fi nani
Ohun alore yi,
Ti ndun l‘eti re tantan
Pe, ―Ronupiwada?‖

3 mf Abana eplu Farpar;


Le je odo mimo,
Sugbon ase ‗wenumo,
Jordan‘ nikan l‘o ni;
Ju ero re s‘apakan,
Se ase Oluwa,
Wa sinu adagun yi,
We, k‘o si di mimo.

4 mf Kin‘ iba da o duro?


Awawi kan ko si;
W‘odo, wo Johannu re,
Ohun gbogbo setan:
O pe ti o ti njiyan,
O ha ba Emi ku?
Elese, gbo alore,
Si ronupiwada
Amin.

490 9.7.10.7. & Ref.


Eje Jesu Kristi Omo Re ni
nwe wa nu kuro ninu ese
wa gbogbo. IJn. 1:7.

1f Agbara mbe n‘nu eje Jesu,


‗Tori o w‘ese mi nu;
Mo si mo pe isin Re li ayo,
O s‘okun mi di ‘mole
ff Agbara mbe, agbara t‘o sise ‘yanu
Agbara mbe; agbara ti o nwe wa mo
Mbe ninu eje Jesu.

2 mf Agbara mbe n‘nu eje Jesu


O gba mi LOWO ebi,
‘Gbati mo k‘eru ese mi to wa
Eje Re si we mi mo

3f Emi mo ire t‘eje na nje,


O ti so wa di titun
Nipa eje Re iyebiye na,
Mo di mimo titi lae.
Amin.

491 L.M.
Emi li onje iye na. Jn. 6:48.

1 f Jesu, ayo okan gbogbo,


Orisun ‘ye, imole wa,
di Nin‘ opo bukun aye yi,
cr Laini ‗telorun, at‘O wa.

2 f Otito Re duro laelae


p Won gb‘awon to kepe O la;
cr Awon ti o wa O ri O,
f Bi gbogbo nin‘ohun gbogbo.

3 f A to O wo Onje Iye,
A fe jel‘ara Re titi;
A mu ninu Re, Orisun,
Lati pa ongbe okan wa.

4 p Ongbe Re sa ngbe okan wa


Nibikibi t‘owu k‘awa;
cr ‘Gbat‘a ba ri O awa yo,
f Ayo nigbat‘ a gba O gbo.

5 mp Jesu wa ba wa gbe titi,


Se akoko wa ni rere;
cr Le okunkun ese kuro,
ff Tan ‘mole Re mimo s‘aye.
Amin.

492 C.M.
E ma se eyi ni iranti mi.
Lk. 22:19.
1 mf Gege bi oro ore Re,
Ninu irele nla;
Emi o se yi Oluwa,
p Emi o ranti Re.

2 mf Ara Re ti a bu fun mi
Yio o je ounje mi;
Uno gba ago ibukun Re
p Lati se ranti Re

3 mp Mo le gbagbo Gethsemane,
Ti mo r‘ijamu Re,
pp Iya on ogun eje Re,
cr Ki nma si ranti Re.

4 Gba mo ba nwo agbelebu,


Ni oke Kalfari;
‘WO Od‘agutan Olorun
Dandan, un o ranti Re

5 mp Un o ranti gbogbo ‘rora Re,


At‘ ife Re si mi,
Cr Bi o ku emi kan fun mi,
Emi o ranti Re.

6 pp Gbati enu mi ba pamo,


Ti lye mi ba ra;
Cr Ti o ba de n‘ijoba Re,
Jesu jo ranti mi.
Amin.

493 6.6.6.6.
Onje na ti emi o si fifunni li
ara mi, fun iye araiye. Jn. 6:51.

1 p Mo nkebi on ongbe,
cr Jesu, se onje mi;
f Tu jade om‘iye,
Lat‘ inu apata.

2p ‘Wo akara t‘a bu


Te okan mi l‘orun,
cr B‘ati b‘okan iye,
mf Bo mi, ma je ki nku.

3 mp ‘Wo Ajara iye,


Je ki nmo adun Re;
cr Jo, tun okan mi se,
mf Fi ife s‘aya mi.
4 p Ona aikuna po,
Ti mo ti rin koja:
cr Bo mi Onje Orun,
di Gba mi, Om‘Olorun.

5 mf Aginju wa sibe,
Ti y‘o m‘ongbe gbe mi;
F Eyin omi iye,
Ema sun ninu mi
Amin.

494 7.8.7.8.7. & Ref.


Eje Jesu Kristi ni nwe wa nu
kuro ninu ese wa gbogbo.
IJn. 1:7.

1 f Kil‘o le w‘ese minu,


Ko si lehin eje Jesu;
Ki l‘o tun le wo mi san,
Ko si lehin eje Jesu.
mp A! eje ‘yebiye,
To mu mi fun bi sno
Ko s‘isun miran mo.
Ko si lehin eje Jesu

2 f Fun wenumo mi, nko ri


‘Kan mi, lehin eje Jesu;
Ohun ti mo gbekele
Fun ‘dariji, l'eje Jesu

3 p Etutu f‘ese ko si,


Ko si lehin eje Jesu,
lse rere kan ko si,
Ko si lehin eje Jesu.

4 mp Gbogbo igbekele mi,


Ireti mi l‘eje Jesu;
Gbogbo ododo mi ni,
Eje, kiki eje Jesu.
Amin.

495 10.10.
Fi eti si mi, Oluso-agutan Israeli,
Iwo ti o nda Josefu bi owo-agutan.
OD. 80:1.

1 mf ‘Wo Oba aanu, lat‘ ori ‘te Re.


Fi ife wo wa, si gbo igbe wa.
2 mp ―Wo Olusagutan eniyan Re,
Pa awon agbo agutan Re mo

3 p Olugbala, iku Re n‘iye wa,


F‘iye ainipekun fun gbogbo wa.

4 cr Onje orun, Iwo ni onje wa,


Se ‘ranwo okan wa nigba ‘ponju;

5 p ‘Wol‘Alabaro, Ore elese.


cr ‘WO n‘ibu ayo wa titi laelae.

6 f Wa f‘ore-ofe Re mu ‘nu wa dun,


Si je k‘a ma ri ojurere Re.

7 mf Nigba osan, ati nigba oru,


Sunmo wa, k‘o s‘okun wa d‘imole.

8 cr Ma ba wa lo, k‘O si ma ba wa gbe,


N‘iye, n‘iku, ma je itunu wa.

9 mf L‘ojojumo f‘oju ‘fe Re to wa,


Si mu wa dele wa l‘alafia.
Amin.

496 7.7.7.7.D.
Oluwa Odo tali awa o lo?
Jn. 6:68.

1 mf Tal‘ awa iba to lo


Biko s‘ odo Re Jesu?
‘Wo ti se imole wa,
At‘iye ainipekun
mp Emi Re ti l‘owo to
T‘Emi Mimo nmi si wa?
Onje Re Atorunwa,
Li okan atunbi nfe.

2 mf Israeli li atijo,
Won je manna, won si ku;
Awon t‘o je l‘ara Re
Won ki y‘o kebi laelae
mp Tal‘ awa iba to lo
‘Gbat‘ ibi ba yi wa ka?
cr Bikos‘ odo Re Jesu
‘Wo tise iranwo wa.

3 mf Tal‘ o le we okan wa,


T‘o si le gbo igbe wa?
Tani le kun okan wa
Olugbala, lehin Re,
F Iyin at‘ope fun O Titi,
‘Wo Olorun mi;
Ninu Re le mi o ma wa,
Ma wa ninu mi titi.
Amin.

497 10.10.10.10.
Emi o siferan Re, emi o si fi
ara mi han fun U. Jn. 14:21.

1 mf Oluwa, mo mba O pade nihin


Igbagbo mu mi wo ohun orun
Uno fi agbara ro mo ore Re,
p Uno si fi ara are mi ti O.

2 mf Emi‘O je akara Olorun,


Emi o mu waini orun pelu Re,
Nihin, un o so eru aye kale,
Nihin, un o gba idariji ese

3 Emi ko ni ‘ranwo mi lehin Re,


Apa re l‘o to lati f‘arati,
cr O to wayi, Oluwa mi, o to,
Agbara mi mbe ninu ipa Re.

4 cr Temi ni ese, Tire l‘ododo,


cr Temi l‘ebi, Tire l‘eje ‘wenu,
mf Ewu abo, on alafia mi
L‘eje at‘ododo Re Oluwa.

5 Gbat‘ a ba dide t‘a si palemo


T‘a ko akara ati wain‘ kuro;
Sibe IWO wa nihin, Oluwa;
Lati je orun ati asa mi.

6 di Bi ase yi ti nde ti o si nlo,


cr O n ran wa leti ase nla t‘orun;
f O nfi ayo didun ase na han
Ase ayo, ‘yawo Od‘ Agutan.
Amin.

498 10.10.
Ara mi tia fifun nyin ni eyi,
E ma se eyi ni iranti mi. Lk. 22:19.

1 mp Sunmo ‘hin, k‘o gba Ara Oluwa,


K‘o mu eje mimo t‘a ta fun O

2 mp Ara at‘eje na l‘o gba o la


cr N‘itura okan, f‘ope f‘Olorun.

3 f Elebun igbala, Omo Baba,


Agbelebu Re fun wa n‘isegun.

4 di A fi On rubo fun tagba tewe,


On tikare, l‘ebo, On l‘alufa.

5 mf On l‘Oludande, On ni Imole,
On nf‘Emi ran awon tire lowo.

6 mp Nje e fokan igbagbo sunmo, ‘hin,


Ki e si gba eri igbala yi.

7 mf On l‘o nsakoso eeyan Re laye,


On l‘o nf‘ iye ainipekun fun wa.

8 f On nfonje orun fawon t‘ebi npa,


Omi iye fun okan ti n pongbe.

9 p Onidajo wa, Olugbala wa,


Pelu wa ni ase ife Re yi
Amin.

499 7.7.7.D.
Enyin fi iku Oluwa han titi yio fide.
I Kor. 11:26.

1 cr K‘On t‘o de, — je k‘oro yi


Ma dun titi l‘eti re;
Je ki sa a die t‘o ku
Han gbangba daju fun O;
F Ronu b‘orun on ile
di ‗Ti d‘ehin gbat‘O ba de.

2 p Gbat‘ awon ti a feran


BO si ‘sinmi won loke,
T‘o je pe aye wa pin,
Ti adun re si koro;
di E dakun, e ma b‘ohun
cr Kiki k‘On to de so ni.

3 mp Ibanuje yi wa ka,
A ha fe k‘o dinku bi?
Gbogbo eru iponju
Gbogbo ofo aye yi,
Iku, ofo on ‘boji
p Nso jeje pe, ‘K‘ On t‘o de.

4 mf Wo tabil‘ ife t‘a te,


Mu waini, si j‘akara;
‘Ranti didun, k‘Oluwa
To pe wa s‘onje orun,
p Ni lat‘aye ‘mi l‘orun,
cr Woon pinya tit‘ On fi de.
Amin.

500 C.M.
Nwon si nrohin nkan ti o se
li ona ati bi o ti di mimo fun
won ni bibu akara Lk. 24:25.

1 mf F‘arahan wa n‘ibi onje,


Ma si se lo nihin;
Olugbala ba wa joko,
Ko si ba wa jeun.

2 f Fi ife mimo ba wa jeun;


K‘ara on eje Re,
Onje iye, waini t‘orun
Ma bo wa titi lae.
Amin.

501 7.7.7.
Jesu wi fun won pe, E wa
jeun owuro Jn. 21:12.

1 mf Jesu, Iwo t‘o pe wa


Si tabili Onje Re;
Fi onje iye bo wa

2 mp B‘a ti f‘irele kunle


Je k‘a mo p‘O sun mo wa;
Si fife nla Re han wa.

3 mp B‘a ti nwo agbelebu,


p T‘a si nkanu ese wa,
So ‘banuje wa d‘aye

4 mp Nigbat‘ a ba mu waini
Ti ns‘ apere eje Re.
2cr Fife Re kun okan wa.

5 f Fa wa si bi iha Re,
Nibiti isun ti nsan,
Si we gbogbo ese wa.

6 p Jo tu ide ese wa
Si busi igbagbo wa,
F‘alafia Re fun wa,
7 cr Ma fi owo Re to wa,
mf Tit‘ ao fi yi ‘te Re ka.
F N‘ile t‘odara julo
Amin.

502 11.9.11.9. & Ref.


O fi eje Re we wa nu kuro
ninu ese wa gbogbo. Ifi. 1:5.

1 mf O ti to Jesu lo fun ‘wenumo bi?


A we O n‘n‘ eje Od‘agutan?
Iwo ha gbekele ore-ofe Re?
A we O n‘n‘ eje Od‘agutan?
A we O n‘nu eje
Ninu eje ti nwe okan mo?
Aso re ha funfun, o si mo laulau?
A we o n‘n‘eje Od‘agutan?

2 mf O mba Olugbala rin l‘ojojumo


A we'o n‘n‘eje Od‘agutan?
O ha gbekele Eni t‘a kan mo ‘gi?
A we o n‘n‘eje Od‘agutan?

3 mf Aso re ha mo lati pade Jesu?


A fo mo n‘n‘ eje Od‘agutan
Okan re ha mura fun ‘le didan ni?
K‘a we o n‘n‘eje Od‘agutan?

4 mp Bo ewu eri-ese si apakan,


K‘a we o n‘n‘eje Od‘agutan?
Isun kan san fun gbogbo okan aimo,
Jo lo we n‘n‘eje Od‘agutan.
Amin.

503 L.M. & Ref.


E duro ninu ife mi. Jn. 15:9.

1 mp Kristi mimo, Oluwa mi,


Ife Re ju t‘arayelo;
Ore otito li O je
Mo mo pe Oluwa mi ni,
f Oun je t‘emi, Ore mi owon,
O mba mi gbe nigbagbogbo;
Ogo didan wa yi I ka,
Ju gbogbo re, Oun je t‘emi.

2 mp T‘emi ni, O sa ku fun mi,


O gba mi, O si da mi n‘de,
f Pelu ayo ni mo nke pe,
Ogo ni fun Olorun mi.

3 mf T‘emi ni, O ngbe okan mi


A ki y‘o pinya tit‘aye,
Bi eka l‘ara ajara
Beni mo je l‘ara Kristi.

4 cr Lojo kan ni ‘lu didan ni,


Oju mi y‘o ri ogo Re;
F Nigbana un o ro mo l‘orun,
Un o fo f‘ayo p‘On je t‘emi.
Amin.

504 H.C. 437. t. H.C. 141.3.7s.


Lati mo ife Kristi to poju imo
gbogbo lo. Efe. 3:19.

1 mp Jesu, ‘WO oninure


Sin wa lo tabili Re
Si f‘onje orun bo wa.

2 cr B‘a ti kunle yi O ka:


Je, ka mo p‘O sunmo wa;
Si fife nla Re han ni.

3 Gb‘aba nfigbagbo wo O
T‘a si nsokun ese
So aro wa di ayo.

4 Gbat ta ba fenu kan wain‘,


Ti ni nsapere Eje Re,
M‘okan wa kun fun ife.

5 Fa wa sibi iha Re,


Nibiti isun ni nsan
Si we gbogbo ese nu.

6 Jo tu ide ese wa
Si busi igbagbo wa
F‘alafia Re fun wa.

7 mf Ma f‘owo Re to wa nso,
Tit‘ao fi de ‘bugbe Re
N‘ile to dara julo.
Amin.

505 C.M.
Emi ki yio mu ninu eso ajara yi mo,
titi yio fi di ojo na, nigbati emi
o si ba nyin mu u ti titun ni
ijoba Baba mi. Mat. 26:29.

1 mf O jo ko‘ ase na leyi,


Mo f‘ara mi fun yin
P E wo, mo feje mi fun yin,
Lati ra yin pada.

2 O di ‘nu ‘joba Baba mi,


Ki nto tun ba yin mu;
‘Gbana ekun ko ni si mo,
A o ma yo titi.

3 mf Titi l‘ao maje onje yi.


K‘o to di igba na;
Ka gbogb‘ aye l‘opolopo
Y‘o ma je, y‘o ma mu'.

4 ‘Bukun atorunwa y‘o ma


Wa lor‘ awon t‘o nje;
Uno gbe or‘ite Baba mi
Ma pes‘ aye fun won.

5 p Sugbon nisisiyi, ago


cr Kikoro l‘em‘ o mu,
Emi o mu nitori yin,
pp Ago rora iku.

6 p E ko le mo banuje mi,
E ko ti r‘ogo mi;
mf Sugbon e ma s‘eyi titi,
K‘e ma fi ranti mi.
Amin

506 S.M.& Ref.


Nitori eyi li eje mi ti majemu titun,
ti a ta sile fun opo enia fun
imukuro Mat. 26:28.

1 mf Isin ‘dapo mimo


Ore-ofe l‘o je
K‘a je akara, k‘u mu wain‘
N‘iranti Re, Jesu.
Fun rant‘ ebo mimo na,
Mimo na, mimo na,
L‘awa pejo po fun l‘oni
Lati f‘lku Oluwa han
Titi Oun.....y'o fide;
Od‘lnu Ijoba Baba mi
Ki nto tun ba yin mu;
N'iru 'dapo be ao ri idande
Gba

N'gba ba ro m‘eje na,


Ogun esu le nde,
A o segun gbogbo won,
Nipa eje Jesu,
Odagutun.

2 Eje ti nsan f‘ese


L‘a r‘apere re yi;
Eri si ni li okan wa
Pe Iwo feran wa

3 A! Eri die yi
Bi o ba dun bayi,
Y‘o ti dun to like orun
N‘gba t‘a ba r‘oju Re

4 Gbana ao mo daju
Pe aworan Re ni wa;
Gbogb‘ona ore ‘yanu Re
Nkede titi aye.
Amin.

507 8.8.8.6. & Ref.


Wo o, awa ti fi gbogbo
re sile Mat. 19:27.

1 mp Mo faye at‘ife mi fun,


Od‘atugan t‘o ku fun mi;
Je ki nleje olotito
Jesu Olorun mi.
p Un o wa f‘Eni t‘O ku fun mi,
Aye mi yo si dun pupo,
Un o wa f‘Eni t‘O ku fun mi;
Jesu Olorun mi.

2 cr Mo gbagbo pe Iwo ngba ni,


‘Tori ‘Wo ku, k‘emi le la;
Emi y‘o si gbekele O,
Jesu Olorun mi.

3 mp Iwo t‘O ku ni Kalfari


Lati so mi d‘ominira;
Mo yara mi s‘oto fun O,
Jesu Olorun mi
Amin.

508 L.M.
Bikosepe enyin ba je ara
Omo enia, ki enyin ki o si mu
eje Re, enyin ko ni iye
ninu nyin. Jn. 6:53.

1 mp Jesu a teriba fun O


A mo p‘O mu oro Re se
A gbo ohun Re a si si
Okan wa lati gba O si.

2 cr Wole wa, Alejo orun


Layo si ohun t‘O fun wa
Ba wa je ninu ebun Re
So okan ‘kanu d‘ile Re.

3 Jo tewo gba adura wa


K‘O si gba ebo iyin wa
F‘omije wa s‘iranti Re
Simi n‘nu ‘fe ‘rapada Re.

4 mf K‘ajoko labe iji Re


Pe wa l‘ore at‘ olufe
Je k‘a je k‘a si mu lofe
K‘a ni ‘telorun lodo Re.

5 mp Je k‘a je ninu ore Re


K‘a jeran Re k‘a m‘eje Re
Ohun mimu li eje Re
Onje orun li ara Re.

6 mf Gbagbo nfonje orun bo wa


L‘o nfi ore ofe to wa.
A nfi O s‘onje lokan wa
A mo pe orun mbe n‘nu Re
Amin.

509 11.10.11.10.
Sugbon ki olukuluku nyin
ki o fe ran aya re be gege
bi on tikara re. Efe. 5:33.

1 mf Ife pipe, t‘o tayo ero eda,


Niwaju Re l‘a wole l‘adura
Pe, ki ife ailopin le je t‘awon
Ti IWO SO d‘okan titi aye.

2 mf Iye pipe, ma je igbekele won


Fun ife on igbagbo ododo;
Fun ireti on emi ifarada,
Pelu ‘fokantan lai beru iku.
3 cr Fun won l‘ayo ti nbori ibanuje
Fun won l‘alafia ti n m‘aye dun,
Titi owuro ologo y‘o fi mo;
Ojo ife on iye ailopin.
Amin.

510 7.6.76.
Olorun si sure fun won. Gen. 1:28.

1 mf Ire t‘a su ni Eden


N‘igbeyawo ‘kini;
Ibukun t‘a bukun won
O wa sibe-sibe

2 Sibe titi di oni


N‘igbeyawo Kristiani;
Olorun wa l‘arin wa,
Lati sure fun wa.

3 Ire ki won le ma bi
Ki won ko si ma re;
Ki won ni ‘dapo mimo
T‘enikan k‘yo le tu.

4 p Ba wa pe, Baba orun,


F‘obirin yi f‘oko;
Bi O ti fi Efa fun
Adam l‘ojo ‘kini.

5 p Ba wa pe, Imanueli
cr Si so oWO won po;
B‘eda meji ti papo
L‘ara ijinle Re

6 p Ba wa pe, Emi mimo;


cr F‘ibukun Re fun won;
Si se won ni asepe
Gege b‘O ti ma se.

7 mf Fi won s‘abe abo Re


K‘ibi kan ma ba won;
‘Gba won npara ile Re
Ma toju okan won.

8 Pelu won loj‘aye won


At‘oko at‘aya;
Titi won o d‘odo Re
N‘ile ayo l‘orun.
Amin.
511 8.6.8.4.
Simi ninu Oluwa, ki o si fi
suru duro de E. OD. 37:7.

1 mp Simi le Oluwa - E gbo


Orin duru orun;
cr Simi le‘fe Re ailopin;
p Si duro je.

2 mp Simi, Iwo oko t‘o gbe


Iyawo re loni;
Ninu Jesu, ‘yawo re ni
Titi aye.

3 mp At‘iwo ti a fa owo re
F‘oko n‘nu ile yi;
Simi, Baba f‘edidi Re
Si eje yin.

4 mf E simi eyin ore won,


T‘e wa ba won pejo;
Olorun won ati ti yin
Gba ohun won.

5 Simi; Jesu oko Ijo


Duroti yin nihin;
Ninu idapo yin, O nfa
p Ijo mora.

6 mp E simi Adaba mimo,


M‘oro Re se n'nu wa,
cr Simi le‘Ife Re ailopin;
p Si duro Je.
Amin

512 7.6.7.6.D.
Ohun ti Olorun ba so sokan,
ki enia kio mase ya won. Mat. 19:6.

1 mf Baba, Eleda gbogbo,


Ninu ogbon Re nla;
Lo so awon meji po
Ninu ogba Eden;
F Fifun awon ‘mo Re yi;
Ife atorun wa,
K‘ibukun wa n‘ile won,
Ile t‘Olorun ngbe

2 mp N‘igbeyawo Galili,
Iwo ba won pejo
Jo, sokale s‘arin wa,
Bukun oko, aya;
cr So ikoro di adun,
So ekun di erin;
Ko won lati mo O li
Onise iyanu.

3 p Emi Orun alaye,


Mi si won lat‘oke;
Fun won ni iwa-mimo,
Fun won n‘ife pipe,
Jo, ma je amona won,
Ki won le sa fese
Se akoso aye won,
Ki won le dabi Re.

4 cr B‘lwo ko ko ile na,


Wuhala asan ni;
B‘IWO ko si n‘ile won,
Asan ni ayo won;
Mf Sugbon ile T‘IWO wa
Idapo didun ni;
‘Biti ife Re ba wa;
Ife ailopin ni.
Amin.

513 8.8.8.6.
Beni Olorun da enia
t ‘ako, t ‘abo O si sure fun nwon.
Gen. 1:27 & 28.

1 mp Olorun ife, a juba,


Gba 'dura awon meji yi
Ti a so po l‘Okan, l‘ara
Mu won je ‘kan n‘nu Re.

2 mf ‘Gbati gbogb‘ ojo kun fayo


Ati‘imole t‘ona si gun;
Nipa igbagbo ni airi,
Mu won je ‘kan n‘nu Re.

3 p ‘Gbat‘igbi ‘danwo n bilu won,


T‘o dabi pe gbogbo re pin,
Ni gbigbeke le O nikan,
Mu won je ‘kan n‘nu Re.

4 mf Eyi t‘oje‘pin won l‘aye


Ayo ni tabi ikoro,
Nipa ipa, or‘-ofe Re,
Mu won je ‘kan n‘nu Re.
5 f Ife ailopin, ba won gbe,
Je alabo won titi lae,
N‘tori ‘ku kole pin niya
Awon t‘Iwo so po
Amin.

514 7.6.7.6.
Olorun, Olorun wa tikarare
yio bu si fun wa. OD. 67:6.

1 mp Agb‘okan at‘ohun wa
Si Baba Eleda
Nip‘awon ‘ranse Re yi
N‘iyin at‘adura.

2 mp Ayo fun ‘fe t‘a f‘eeyan


Ati ayo t‘oke;
‘Yin fun ‘bukun ainiye,
Ife t‘ota‘feyo

3 mp Adura ki ‘dapo yi
Leje eyi t‘ope;
K‘ife won le je okan,
K‘won si j‘okan ‘nu Re.

4 Adura k‘O s‘asepe


Ileri won oni;
Si bukun oj‘aye won
Ti ao ma ri titi.

5 f Iyin fun ‘reti ogo


T‘o ga ju orun lo,
‘Biti ‘gbagbo y‘o fo lo,
Ti‘fey‘owa titi.
Amin.

515 7.7.7.D.
Nitori eyi li okunrin yio se fi
baba ati iya re sile, on o
si dapo mo ay a re. Efe. 5:31.

1 mf Oluwa, f‘ase Re si
Idapo t‘a njeri yi;
F‘ola Re ba wa pejo,
F‘ileri ‘fe won mule;
So ‘dapo yi di mimo
Fun won ati lodo Re

2 ‘Wo fara han ni Kana


N‘igbeyawo bi eyi;
Ba wa pade nihinyi,
‘Wo orisun ibukun!
Fi ayo t‘aye ko ni
Se ‘gbeyawo yi l‘oso.

3 mf A ko fe ise ‘yanu,
Pe ki omi di waini;
Gbogbo ife okan wa
Ni, k‘a to ife Re wo;
K‘agbara lat‘oke wa
So ‘fe aye di mimo.

4 mf Lat‘ oni lo, Oluwa,


Jek‘ ajo t‘oko t‘aya,
B‘oti le wu k‘o gun to,
De opin li odo Re;
cr Ni ile isimi ni,
f Ni ile Re li orun.
Amin.

516 6.6.4.6.6.6.4.
Ko dara ki okunrin na ki o
nikan ma gbe emi o se oluranlowo
ti o dabi re fun u. Gen. 2:18.

1 f Krist‘ n‘nu ogba Eden,


L‘a gbe ti r‘ase yi,
Ase Tire,
P‘o ye f‘eni meji
Ki won jo ma gbe po,
Ki won jo ma rin po
Ninu aye.

2 mp Nje a k‘ara wa jo,


Lati se ase yi:
T‘ojo kini;
p Jo, ma sai sokale,
K‘O wa si arin wa,
Pelu ibukun Re;
Sokale wa

3 mp K‘awon mejeji yi,


T‘a fe lati so po,
Le wa fun O
N‘gba gbogbo ma ko won
N‘ise won s‘ara won,
Ki won si le repo
Tit‘ aye won.
Amin.
517 C.M.
A si pe Jesu ati awon omo
ehin re pelu si ibi iyawo. Jn. 2:2.

1 mf N‘ilu Kana ti Galili,


Nib‘ ase ‘gbeyawo,
Jesu fara Re han nibe,
Pel‘awon ‘mo-ehin.

2 p Jesu masai fara Re han


Nibi ‘gbeyawo yi,
K‘O si fi ibukun Re fun
Oko ati aya.

3 p Jeki won lewa n‘irepo,


Ni ojo aye won;
K‘ife at‘orun wa so won,
K‘aye ma le ja won.

4 p Ki won ma ran ‘ra won lowo


Nipa ajumose;
Fi alafia Re kun won,
Fun won n‘i telorun.

5 p Gege b‘ire ojo kini,


Ni ogba Edeni,
Ki won ma bi, ki won ma re,
Tit‘ opin emi won;
Amin.

518 C.M.
A si pe Jesu ati awon omo
ehin re pelu si ibi igbeyawo Jn. 2:2.

1 mf Jesu f‘ara han nitoto


Nibi ase ‘yawo
Oluwa, awa be O, wa
F‘ara Re han nihin

2 Fi ibukun Re fun awon


Ti o da ‘wopo yi;
F‘oju rere wo ‘dapo won,
Si bukun egbe won.

3 F‘ebun Ife kun aya won,


Fun won nl 'telorun;
Fi alafia Re fun won,
Si busi ini won.
4 F'lfe mimo so won d‘okan
Ki won f‘ife Kristi
Mu aniyan ile fere;
Nipa ajumose

5 Je ki won ran ‘ra won lowo


Ninu igbagbo won;
Ki won si ni omo rere,
Ti y‘o gbe ‗le won ro
Amin.

519 6.5.6.5.
IWO O dubule, orun re
yio si dun. Owe. 3:24.

1 mp Ojo oni lo tan


Orun sunmole;
Okunkun ti de na,
Ile si ti su.

2 Okunkun bo ile,
Awon ‘rawo yo;
Eranko at‘eye
Lo si ‘busun won.

3 mf Jesu f‘orun didun


F‘eni alare;
p Je ki ibukun Re
Pa oju mi de.

4 cr Je k‘omo kekere
La ala rere;
S‘oloko t‘ewu nwu
Ni oju omi.

5 p Ma toju alaisan
Ti ko r‘orun sun;
mf Awon tinro ibi
Jo, da won l‘ekun.

6 p N‘nu gbogb‘ ewu oru,


Te k‘angeli Re
Mase olusomi
Lori ‘busun mi.

7 mp ‘Gba‘ ile ba si mo
Je k‘emi dide
F B‘omo ti ko l‘ese
Ni iwaju Re.
8 ff Ogo ni fun Baba,
Ati fun Omo,
Ati f‘Emi Mimo
Lae ati laelae.
Amin.

520 C.M.
Omo na si ndagba, o si
N lagbara Lk. 2:40.

1 mf Bi osun gbege eti ‘do,


Tutu mini-mini;
B‘igbo dudu eti omi,
B‘itanna ipado.

2 Be l‘omo na yoo dagba


Ti nrin l‘ona rere;
T‘okan re nfa si Olorun
Lat‘ igba ewe re.

3 di Ewe tutu l‘eba odo


p B‘o pe, a re danu;
Be n‘itanna ipa omi
Si nre l‘akoko re.

4 cr Ibukun ni fun omo na


Ti nrin l‘ona Baba;
f Oba ti ki pa ipo da,
Eni mimo laelae.

5 mf Oluwa, ‘Wo l‘a gbekele,


Fun wa lore-ofe;
cr L‘ewe l‘agba ati n‘iku,
Pa wa mo b‘Omo Re.
Amin

521 6.5.6.5
Tani ha kegan ojo ohun kekere?
Sek. 4:10.

1 mf Opo ikan omi,


‗Yanrin kekere,
‗Wonyi l‘od‘okun nla
At‘ile aye

2 mp Iseju wa kokan
Ti a ko ka si
cr L‘o nd‘odun aimoye
Ti ainipekun.
3 mp Iwa ore die,
Oro‘fe die,
cr L‘o ns‘aye di Eden
Bi oke orun.

4 p Isise kekeke
L‘o n m‘okan sina,
Kuro l‘ona rere
Si ipa ese.

5 mf Ise anu die


T‘a se l‘omode
cr Di ‘bukun forile
T‘o jinna rere.

6 f Awon ewe l‘ogo


Ngberin angeli;
Se wa ye, Oluwa
p F‘egbe mimo won.
Amin.

522 11.11.11.11
Emi li oluso agutan rere.
Jn. 10:11.

1 mf Oluso-agutan l‘Olugbala wa,


B‘a ba wa l‘aya Re kil‘ a o beru,
Sa je k‘a lo s‘ibiti O nto wa si,
Ibaje asale tab‘oko tutu.

2 Oluso-agutan awa m‘ohun Re


p Wo b‘oro kele Re ti nm‘okan wa dun;
B‘o tile mba wa wi jeje l‘ohun Re,
Laisi Re l‘ehin wa awa o segbe.

3 p Oluso-agutan ku f‘agutan Re,


cr O feje Re won awon agutan Re,
O si fi ami Re s‘ara won, o ni;
―Awon t‘O l‘Emi Mi, awon ni t‘Emi‖.

4 mf Oluso-agutan, l‘abe iso Re,


Bi koriko ba wa, ki y‘o le se nkan;
p Bi awa tile nrin l‘ojiji iku,
Awa ki y‘o beru, awa o segun.
Amin.

523 6.5.6.5.
E o si mo otito, otito yio si so
nyin di Ominira. Jn. 8:32.
1 mf Jesu Onirele,
Omo Olorun,
Alanu, Olufe,
p Gbo ‘gbe Qmo Re

2 p Fi ese waji wa,


Si da wa n‘ide,
Fo gbogbo orisa,
Ti mbe l‘okan wa.

3 f Fun wa ni omnira,
cr Fife s‘okan wa;
Fa wa, Jesu mimo
S‘ibugbe l‘oke.

4 To wa l‘ona ajo,
Si je ona wa
La okun aye ja
S‘imole orun.

5 mf Jesu Onirele,
Omo Olorun,
Alanu, Olufe,
Gbo ‘gbe Omo Re
Amin.

524 7.6.8.6.
E si ma ko eko lodo mi,
nitori oninu tutu ati onirele
okan li emi. Mat. 11:29.

1 mf Mo fe ki ndabi Jesu
Ninu Iwa pele;
Ko s‘eni t‘o gb'oro ‘binu
L‘enu Re lekan ri.

2 Mo fe ki ndabi Jesu
L‘adura ‘gba gbogbo; v
p Lori oke ni On nikan
Lo pade Baba Re.

3 mf Mo fe ki ndabi Jesu
Emi ko ri ka pe;
Bi nwon ti korira Re to
Ko s‘enikan ni ‗bi.

4 Mo fe ki ndabi Jesu
Ninu Ise rere;
K‘a le wi nipa t‘emi pe;
―0se ‘won t‘o le se.
5 Mo fe ki ndabi Jesu
T‘o f‘iyonu wipe,
―Je k‘Omode wa s‘odo mi,‖
Mo fe je ipe Re

6 p Sugbon nko dabi Jesu,


O si han gbangba be;
cr Jesu fun mi l‘ore-ofe,
Se mi, ki ndabi Re.
Amin.

525 7.7.7.7
O gbe owo Re le won
O si sure fun won Mk. 10:16.

1 mf Jesu fe mi, mo mo be,


Bibeli l‘o so fun mi;
Tire l‘awon omode,
f Won ko l‘agbara On ni.

2 p Jesu femi En‘t‘O ku


Lati si orun sile;
mf Yio we ese mi nu;
Je ki omo Re wole

3 p Jesu fe mi sibe si,


Bi emi tile s‘aisan;
L‘or‘akete aisan mi
cr Y‘o t‘ite Re wa so mi.

4 mf Jesu fe mi, y‘o duro


Ti mi ni gbogb‘ ona mi:
‘Gba mba f‘aye yi sile,
Y‘O mu mi rele orun.
Amin.

526 8.6.8.5. & Ref.


Nwon o si je temi, li Oluwa
awon omo ogun wi, li ojo na
nigbati mo ba nsiro oso mi
Mal. 3:17.

1 mf ‗Gbat‘ O ba t‘ O ba de ‘gba t‘O ba de


Lati sir‘ oso Re;
Gbogbo oso Re iyebiye,
Awon ti O fe.
f Bi irawo owuro, won ns‘ade Re loso
Ewa won oyo pupo, ewa f‘ade Re.
2 mf Yio ko jo, yio ko jo,
OSO ijoba Re;
Awon mimo, awon didan,
Awon ti O fe.

3 mf Awon ewe, awon ewe,


T‘o fe Olugbala;
Ni oso Re iyebiye,
Awon ti O fe.
Amin.

527 8.7.8.7.7.7.
A si bi Jesu ni Betlehemu
ti Judea. Mat. 2:1.

1 mf Nigba kan ni Betlehemu,


Ile kekere kan wa,
Nib‘iya kan te ‘mo re si,
Lori ibuje eran;
Maria n‘iya omo na,
Jesu Krist si l‘omo na.

2 O t‘orun wa s‘ode aye,


On l‘Olorun Oluwa;
O file eran se ile
‘Buje eran fun ‘busun;
Lodo awpn otosi,
Ni Jesu gbe li aye.

3 Ni gbogbo igba ewe Re,


O ngboran, O si mb‘ola;
O feran, O si nteriba,
Fun iya ti ntoju Re!
O ye ki gbogb‘ omode
K‘o se olugboran bo

4 ‘Tori On je awose wa,


A ma dagba bi awa;
O kere ko le da nkan se,
p A ma sokun bi awa;
O si le ba wa daro,
f O le bawa yo pelu.

5 A o f‘oju wa ri nikehin
Ni agbara ife Re;
Nitori omo rere yi
Ni Oluwa wa l‘orun;
O nto awa omo Re
S‘ona ibiti On lo.
6 f Ki se ni ibuje eran
Nibiti malu njeun
L‘awa o ri, sugbon l‘orun
LOWO otun Olorun;
‘Gba won ‘mo Re b‘irawo
Ba wa n‘nu aso ala.
Amin.

528 8.6.7.6.7.6.7.6,
Ti nyin ni gbogbo won, enyin
ni ti Kristi. I Kor. 3:22 & 23.

1 mf Ore kan mbe fun omode


Loke orun lohun;
Ore ti ki yi pada,
T‘ife Re ko le ku;
p Ko dabi ore aye
Ti mbaje l‘ododun;
f Ore yi ye lati je
Oruko Re Owon

2 mp Isimi kan mbe f‘omode


Loke orun lohun;
F‘awon t‘o f‘Olugbala
Ti nke ―Aba Baba‖,
di ‘Simi lowo iyonu,
Low‘ ese ati ewu;
Nibi awon omode
p Y‘o simi titi lae.

3 mf Ile kan mbe fun omode


Loke Orun lohun;
f Nibiti Jesu njoba
Ile alafia!
di Ko s‘ile to jo l‘aye
T‘ale fi s‘akawe;
f Ara ro ‘lukuluku;
Irora na d‘opin

4 cr Ade kan mbe fun omode


Loke orun lohun;
Eni t‘o ba nwo Jesu,
Y‘o ri ade na de;
Ade t‘o fi fun gbogbo
Ti y‘o fi fun gbogbo
mf Awon t‘o wa oju Re
Ti won si fe nihin.

5 f Orin kan mbe fun omode


L‘oke orun lohun;
Orin ti ko le su ni,
B‘o ti wu k‘a ko to!
mf Orin t‘awon angeli
Ko le ri ko titi;
Krist‘ ki s‘Olugbala won
Oba l‘o je fun won.

6 f Ewu kan mbe fun omode


Loke orun lohun;
Harpu olohun didun!
Imo ‘pe isegun;
Gbogbo ebun rere yi
L‘a ni ninu Jesu;
p Ewa eyin omode,
Ki won le je ti yin
Amin.

529 6.6.6.6.8.8.
Ma wi, Oluwa, nitori iranse
Re n gbo. I Sam. 3:9.

1 mf ‗Gbati Samuel‘ ji
To gbo ohun Eleda
Ni gbolohun kokan,
Ayo ro ti po to!
Ibukun ni f‘omo t‘o ri
Olorun nitosi re be.

2 B‘Olorun ba pe mi
Pe, On li Ore mi;
Ayo mi y‘o ti to,
Un o si f‘eti sile;
Un o sa f‘ese t‘o kere ju
B‘Olorun sunmo ‗tosi be

3 Ko ha nba ni soro?
Beni, n‘nu oro Re
O n pe mi lalti wa
Olorun samuel,
N‘nu Iwe na ni mo ka pe
Olorun Samuel npe mi.

4 Mo le l‘ori pamo
S'abe itoju Re;
Mo mo p‘Olorun mbe,
L'odo mi n ‗gbagbogbo;
O ye k‘eru ese ba mi
N‘tor‘Olorun sunmo ‘tosi.

5 ‗Gba mba nka oro Re,


Ki nwi ni Samuel pe
"Ma wi, Oluwa mi
Emi y‘o gbo Tire‖
‘Gba mo ha si wa nile Re,
Ma wi, ‘tori ‘ranjp Re ngbo.
Amin.

530 C.M.
Nitori ibi hiha li enu ona na ati
toro loju ona na ti o lo si
ibi iye Mat. 7:14.

1 mf Ona kan lo ntoka s‘orun


Isina ni ‘yoku
Hiha si l‘oju ona na,
Awon Kristian lo fe.

2 Lat‘ aye o lo tarata


O si la ewu lo;
cr Awon ti nfi ‘gboya rin in,
Y‘o d‘orun nikehin

3 mf Awon ewe yo ha ti se
Le la ewu yi ja;
‘Tori idekun po l'ona
F‘awon odomode.

4 p Gbigboro l‘ona t‘opo nrin


O si teju pelu
Mo si mo pe lati d‘ese
Ni won se nrin nibe.

5 mf Sugbon kese mi ma ba ye
Ki nma si sako lo;
Oluwa jo s‘oluto mi,
Emi ki o sina.

6 Nje mo le lo laisi ‘ foya


Ki ngbekel‘ oro Re
p Apa Re y‘o s‘agutan Re
Y‘O si ko won dele.

7 cr Beni uno la ewu yi ja


Nipa itoju Re;
f Un o tejumo ‘bode orun
Titi uno fi Wole.
Amin.

531 C.M. & Ref.


Nwon ti fo aso igunwa won
nwon si so won di funfun ninu
eje Odo-agutan. Ifi. 7:14.

1f Yika or‘ite Olorun


Egberun ewe wa;
Ewe t‘a dari ese ji.
Awon egbe mimo
Nkorin Ogo, ogo, ogo.

2 Wo olukuluku won wo
Aso ala mimo;
Ninu imole ailopin
At‘ ayo ti ki sa.

3 mf Ki l‘o mu won de aye na,


Orun t‘o se mimo;
cr Nib‘ alafia at‘ayo,
Bi won ti se de be.

4p Nitori Jesu ta ‘ je Re
Lati k‘ese won lo;
A ri won ninu eje na,
Won di mimo laulau.

5 mf L‘aye won wa Olugbala,


Won fe oruko Re;
cr Nisisiyi won r‘oju Re,
Won wa niwaju Re.

6p Orisun na ha nsan loni?


Jesu mu wa de be;
K‘a le ri awon mimo na,
K‘a si ba won yin O.
Amin.

532 L.M.
Kristi jiya lekan nitori ese
wa, olotito fun alaisoto ki
o le mu wa de odo
Olorun. I Pet. 3:18.

1 mf Jesu t‘o wal‘oke orun


p Sokale d‘eniyan, O ku;
Ninu Bibeli l‘a le ri
Bi On iti ma se rere.

2 O nkiri, O si nse rere


O nla ‘ju awon afoju;
Opo awon t‘o si yaro
O sanu won, O si wo won.

3 Ju wonni lo, O wi fun won;


Ohun wonni t‘Olorun fe;
O si se Eni t‘o tutu;
Yoo si gbo t‘awon ewe.

4 p Sugbon iku t‘O ku buru;


A fi ko s‘ or‘ agbelebu
OWO rere t‘o se nkan yi,
p Won kan mo‘gi agbelebu.

5 p Be l‘O ku nitori yi na,


O d‘eniyan, ko ba le ku;
Bibeli ni O t‘orun wa,
K‘Ole dari ese ji ni.

6 O mo b‘eniyan ti buru,
O mo b‘iya ese ti ri,
Ninu anu, Jesu wipe,
On ogba iya ese je.
Amin.

533 L.M.
O mu isu akara marun ati
eja meji, O gbe oju soke, Osure,
Osibuu, Osi fi fun awon Omo ehin
Re. Mk. 6:41.

1 mf Wa, ba wa jeun, Oluwa


Je k‘a ma yin oruko Re;
cr Wa bu si onje wa, si je
K‘a le ba O jeun l‘orun.
Amin.

534 L.M.
Gbogbo eda Olorun li o dara
bi a ba fi ope gba a. I Tim. 4:4.
1f A‘fope fun O, Oluwa
Fun onje wa, at‘ebun mi;
Fi onje orun b‘okan wa
Onje iye lat‘ oke wa.
Amin.

535 S.M.
E sunmo Olorun On yio si
sunmo yin. Jak 4:8.

1 f Jesu a w‘odo Re,


L‘ojo Re mimo yi,
To wa wa b‘awa ti pejo,
Si ko wa fun ‘ra Re.

2 p Dari ese ji wa,


Fun wa l‘Emi mimo;
Si ko wa, k‘alo aye wa
K‘a le ye ‘bugbe Re.

3 f F‘ ife kun aya wa,


Bukun oluko wa;
K‘awa at‘ awon le pade
Niwaju Re l‘oke.
Amin.

536 C.M.
Omiran si be si ile rere, o
si so eso Mat. 13:8.

1 mf K ‘awa to pari eko wa,


Awa fiyin fun O;
‘Tori ojo Re mimo yi,
Jesu ore ewe.

2 f Gbin oro Rpe si okan wa,


Gba wa lowo ese.
Ma je k‘a pada l‘ehin Re,
Jesu Ore ewe.

3 Jesu, jo bukun ile wa;


K‘a lo ojo yi re;
K‘A le ri aye lodo Re,
Jesu ore ewe.
Amin.

537 6.5.6.5.
Kojuja si ese, on a si sa kuro
lodo nyin Jak. 4:7

1 mf Mase huwa ese


Ma soro ‗binu;
Omo Jesu l‘e se
Omo Oluwa

2 mf Krist‘ je Oninure,
At‘ Eni Mimo;
Be l‘awon omo Re
Ye k‘o je mimo

3 p Emi ibi kan wa


T‘o nso irin re;
O si nfe dan o wo
Lati se ibi

4 E ma se gbo tire,
B‘o ti le soro
Lati ba esu ja
Lati se rere

5 mf Eyin ti se ‗leri
Ni omo owo;
Lati k‘esu sile
Ati ona re

6 Om‘ ogun Krist‘ niyin,


E ki lati ba
Ese inu yin ja,
E ma se rere

7 f Jesu l‘Oluwa yin,


Cr O se Eni re;
Ki eyin omo Re
Si ma se rere
Amin.

538 C.M.
A won omode si nke ninu
Tempili wipe, Hosanna si
omo Dafidi. Mat. 21:15.

1 f Hosana! e korin s‘oke


S‘omo nla Dafidi
Pelu Kerub‘ ati Seraf,
K‘a yin Om‘Olorun.

2 mp Hosana! eyi na nikan


L‘ahon wa le ma ko!
cr Iwo ki o kegan ewe
Ti nkorin iyin Re.

3 f Hosana! Alufa, Oba,


Ebun Re ti poto!
Eje Re l‘o je iye wa
Oro Re ni onje.

4 mf Hosana! Baba awa mu


Ore wa wa fun O;
Ki ‘se wura tab‘ ojia
Bikose okan wa.

5 Hosana! Jesu lekan ri


O yin awon ewe;
cr Sanu fun wa, si f‘eti si
Orin awa ewe.

6 Jesu b‘O ba rawa pada,


T‘a si wo ‘joba Re;
A o fi fere wura ko
Hosana titi lae.
Amin.

539 8.4.8.4.8.8.8.4
Ore kan si mbe ti o fi ara moni
ju arakunrin lo. Owe. 18:24.

1 mf E nikan mbe t‘O feran wa,


A! O fe wa!
Ife Re ju ti‘yekanlo,
A! O fe wa;
p Ore aye nko wa sile,
B‘oni dun, ola le koro;
cr Sugbon Oro yi ko ntan ni,
A! O fe wa!

2 mf Iye ni fun wa, b‘a ba mo,


A! O fe wa!
di Ro b‘a ti je ni‘gbese to,
A! O fe wa!
P Eje Re l‘O si fi ra wa
Nin‘ aginju l‘O wa wa ri;
cr O si mu wa wa s‘agbo Re;
A! O fe wa!

3 f Oro ododo ni Jesu,


A! O fe wa!
O fe lati ma bukun wa
A! O fe wa!
Okan wa fe gbo ohun Re
Okan wa fe lati sunmo;
On na ko si ni tan wa je,
A! O fe wa!

4 p Loko Re l‘a nri ‘dariji


A! O fe wa!
cr On o le ota wa s‘ehin,
A! O fe wa!
f On o pese ‘bukun fun wa;
Ire l‘a o ma ri titi
ff On o fi mu wa lo s‘ogo,
A! O fe wa!
Amin.
540 C.M.
O si gbe won lapa Re.......
O si sure fun won. Mk. 10:16.

1 mf Wo b‘Olus‘agutan Israel‘
Ti fi ayo duro;
O npe awon Od‘agutan,
O si kowon mora.
On si wipe, ― Je ki nwon wa‖
―E mase k‘egan won‖
Lati sure fun iru won,
L‘Oba angel‘ se wa.

3 f Pelu ope l‘a gbe won wa,


A jewo won fun O,
Ayo: pe awa je Tire
K‘omo wa je Tire.
Amin.

541 7.7.7.7.
Nibe l‘Oluwa gbe pase, ibukun,
ani iye laelae. OD. 133:3.

1 mf Baba orun, k‘ife Re,


Tan s‘ori wa lat‘ oke;
Je k‘omo yi ni ipo
N‘nu majemu ore Re.

2 cr Ba wa pe, sigb‘adura
Jesu, Omo Olorun,
K‘eje Re ti Kalfari
W‘ese ibi omo yi.

3 mp Emi mimo sokale,


Ya omo yi si mimo;
Fi agbara nla Re han,
S‘amona re tit‘ opin.

4 mf Jehofa, Baba, Omo,


Eni meta, Okan ‘so;
K‘ibukun t‘odo Re wa,
Tire ni gbogbo ogo.
Amin

542 6.7.8.6.8.1.1.
E je ki awon omo kekere wa
Sodo mi Lk. 18:16.

1 mf ‘Gba ‘won iya Salem


Gb‘omo won to Jesu wa;
Awon om‘ehin Re le won
Wipe ki won ma lo,
Sugbon ki won to ma salo
f Krist ri won, O f‘ayo wipe;
Je ki awon omo wewe to Mi wa.

2 mp Em‘ o tewogba won,


Un o gbe won mora pelu;
Emi y‘o je Oluso won,
E mase le won lo;
Bi won, ba f‘okan won fun mi,
f Won y‘o ba mi gbe ‘nu ogo,
Je ki awon omo-wewe to Mi wa.

3 mf Olugbala wa seun;
T‘O tewogba ‘won ‘mo na;
Sugbon opo ewe mbe ti
Ko gbo Oko Re ri;
Ti won ko ka Bibeli ri,
mp Nibit‘ Olugbala so pe;
Je ki awon omo-wewe to Mi wa,

4 cr Laipe, ki keferi
Ti mbe ni gbogbo aye
M‘oro Re se, ki won si ko
Orisa won danu,
Jo tan imole Re si won,
f Farahan b‘Olorun ife,
Ko awon 'mo wewe lati to O wa.
Amin.

543 6.5.6.5.
E je awon omo kekere ki o wa
sodo mi, E ma si se da won lekun.
Mk. 10:14.

1 mf Jesu, t‘o po logo,


Jo, deti sile;
Gbo ‘yin awa ewe,
B‘a ti njuba Re

2 B‘O ti je mimo to,


Olodumare,
‘WO y‘o teti sile
Gba t‘a ba yin O.

3 p Omode l‘awa je,


A ko pe sako;
Olugbala, to wa
Si ona orun.

4 cr Gba wa lowo ese;


SO wa lojojo;
Je k‘ a le feran Re
Ko ese wa lo.

5f ‘Gbat‘ O ba si pe wa
S‘ile wa orun;
Layo l‘a o dahun pe;
Oluwa, a de!
Amin.

544 10.4.10.4.10.10.
Ko mi li ona Re Oluwa, ki O si to
mi li ona otito. OD. 27:11.

1 mp Jesu, ‘Wo t‘o npe omode mora,


Mo wa sodo Re;
JO di mi mu, K‘O si ba mi soro
Sin mi rele;
Ki nma ba ya kuro lona iye,
K‘agutan Re ma di ije f‘esu.

2 Mo feran ranti p‘ese mimo Re


Ti rin-na mi.
L‘opopo aye at‘ona hiha
Pel‘Olorun
Pe O muyon ri l‘aya Maria,
Pe O si jise f‘awon obi Re.

3 cr Jesu Onirele, jek‘ Okan mi


T‘o kun f‘ese
Di mimo, lailabawon, bi Tire,
Si ma gbe ‗be
‘Gbana un o mo Olorun Baba mi
Un o ma gberu l‘ogbon at‘agbara.

4 f Olugbala, ‘WO ni un o korin si


Li owuro,
Iyin y‘o so igba ‘banuje mi
D‘igba ayo;
Ninu ‘se ati ninu ere mi,
‘Fe re y‘o je ofin at‘ayo mi.
Amin.

545 1.1.1.1.
Jesu si pe omo kekere kan
sodo R Mat. 18:2.
1 mp Jesu, ‘WO onirele,
Wo mi, emi omode;
JO sanu aimokan mi,
Jek‘ emi wa sodo Re.

2 di Mo fe k‘a mu mi t‘O wa;


Oluwa, mase ko mi;
F‘emi omode l‘aye
N‘ijoba or‘-ofe Re

3 mp O wu mi ki ndabi Re;
Fun mi l‘okan igboran;
‘WO Alanu, Olore,
F‘okan ife Re fun mi.

4 Leke gbogbo re, Jesu,


Je nma se ‘fe Baba mi
Ki nma b‘Emi Re n‘inu
Ki nwa f‘ogo Re nikan.

5 cr Odagutan Olorun
‘WO ni k‘o j‘apere mi,
IWO tutu, ‘Wo tenu;
O si ti s‘omode ri.

6 mf Jesu, Ore omode,


Ni owo Re ni mo wa;
Se mi gege b‘O ti ri
Si ma gbe ‘nu mi titi.

7 f Emi y‘o fi yin Re han


Uno fi aye mi sin O,
Aye y‘o si ri Kristi,
Omo mimo ninu mi.
Amin.

546 7.8.7.8.8.8.
Jesu si wipe, ―e jeki awpn omo
kekere wa si odo mi. Nitori ti
iru won ni ijoba Olorun. ‖ O si
sure fun won. Mk. 10:14 & 16.

1 mf Jesu nihin l‘a duro


Lati se bi IWO ti wi;
Omo yi, ni ase Re,
L‘a fi bun O nisisiyi;
Kristi li a fun l‘omo na;
'Iru won n‘ijoba orun.

2 mp Fun eyi a to O wa,


Gba omo yi ti a mu wa,
Je k‘a r‘ogo Re nihin,
Ni anu se ni omo Re;
Ma si se fi sile laelae
L‘aye ati l‘orun pelu.

3 cr L‘aya Re l‘omo yi wa
Isura owon f‘okan wa,
Je k‘adura wa goke,
Ya ibukun Re l‘ainiwon,
Si ko oruko ti a fun
Omo yi sinu‘we iye.
Amin.

547 C.M.
A won omode nke ni tempili wipe,
Hosana. Mat. 21:15.

1 mf Gba Jesu wo tempili lo,


Ohun iyin l‘a gbo;
Omode jewo eto Re,
f Gbogbo won si nyo si I.

2 ff Hosana mu tempili ro,


Ahon pipo dalu;
Hosana si Oba t‘orun,
S‘ iru mimo Dafidi.

3 Oluwa ‘sojo wa d‘otun,


‘Gbat‘ omode yin O;
Agbara at‘ ore Re po
Bi t‘ojo igbani.
Amin.

548 8.7.8.7.
Emi ni Oluso-agutan rere
Jn. 10:14.

1 mf Jesu, ‘Wo ti mbo agbo Re,


B‘ olus‘agutan rere,
Ti ‘sike awon t‘o dera,
Ti ‘gb‘awon odo mora.

2 mp JOWO! gba omode wonyi,


F‘aanu gba won mo aya;
Gbangba l‘o daniloju pe,
Ewu ki y‘o wu won n‘be

3 Nibe, won ko ni sako mo


Ekun ki y‘o le pa won;
Je ki ‘ronu ife nla Re
Dabo won lona aye

4 N‘nu papa Re oke orun,


Je ki wo ri ‗bi ‗simi
Ki won j‘oko tutu yoyo.
Ki won m‘omi ife Re
Amin

549 C.M.
Iwo Olorun ninu ore Re li o ti
npese fun awon talaka OD. 68:10.

1 mf Olorun, ite ogo Re,


Yio wa titi lae;
Obi wa, talaka ni won,
F‘ibukun Re fun wa.

2 O wu O ni, lati se wa
p Ni talaka; sugbon
Maa se alabojuto wa,
‘Gbati a wal‘aye.

3 A mo, b‘atile je Tire,


T‘ a j' oruko mo O,
A j'alejo; sugbon se wa
L‘omo asayan Re

4 Oluso agutan wa, wo


Agbo kekere Re;
F‘Ogo at‘opa Re to wa,
Omo agbo Tire
Amin.

550 8.7.8.7.D.
Lati enu awon omo-owo, ati omo
omu, ni Iwo ti se ilana agbara.
OD. 8:2.

1 mf Jehofa! Olorun ogo,


Je ki omode yin O;
p A wole n‘irele fun O,
Ore Re ni orin wa,
Ogun Seraf‘ dupo gberin
Ife Re l‘oke orun;
Olorun ogo, gbo tiwa,
B‘a ti nyin oruko Re

2 Imanueli! Iwo t‘a bi,


p T‘a si fi ko or‘ igi,
O pe omode kekere,
Lati wa si odo Re;
Oluwa, b‘o ti pe, a de,
Je k‘ari aanu Re gba!
K‘awa, pel‘ awon omo Re,
K‘a sin O, k‘a si fe O.

3 A ba le wa, k‘a si fe O,
K‘a si beru Rce l‘aye;
Nikehin, k‘a wa pelu Re,
f K‘a ri O, k‘a si yin O,
Jesu! Olorun itunu,
Olori ore! dide,
f Fi igbala Re bukun wa,
JO tewo gba orin wa.
Amin.

551 L.M.
Efi iberu sin Oluwa. OD. 2:11.

1 mf Omode, e sunm‘ Olorun.


p Pelu irele at‘eru;
Ki ekun gbogbo wole fun
Olugbala at‘Ore wa.

2 mf Oluwa, je k‘anu Re nla,


Mu wa kun fun ope si O;
Ati b‘a ti nrin lo l‘aye,
K‘a ma ri opo anu gba.

3 Oluwa! m‘ ero buburu,


Jinna rere si okan wa;
L‘ojojumo fun wa l‘ogbon,
Lati yan ona toro ni.

4 p Igba aisan, at‘ilera


Igba aini tabi oro;
pp Ati l‘akoko iku wa,
f Fi agbara Tire gba wa.
Amin.

552 4.4.8.
Ojo nlo, ojiji ojo ale na jade.
Jer. 6:4.

1 pO Oj‘ oni lo,


Jesu Baba,
Boju Re w‘emi omo Re

2 ‘WO Imole,
Se ‘toju mi;
Tan imole Re yi mi ka.

3 Olugbala,
Nko ni beru
Nitori O wa lodo mi.

4 Nigba gbogbo
Ni oju Re
NSO mi, gbat‘ enikan ko si.

5 Nigba gbogbo
Ni eti Re
Nsi si adura omode.

6 Nitorina
Laisi foya,
Mo sun, mo si simi le O,

7 Baba, Omo,
Emi Mimo
Ni iyin ye l‘orun l‘aye.
Amin.

553 C.M.
E korin si Oluwa. OD. 96:2.

1 Edide ki a si korin,
K‘a yin Oluwa wa,
K‘a si dupe li owo Re,
F‘ anfani idasi.

2 E dide ki a si korin,
K‘a yin Oluwa wa,
K‘a si dupe li owo Re
Fun oro mimo Re.

3 E dide ki a si korin,
K‘a yin Oluwa wa,
K‘a be E fun ‘ranwo orun,
T‘aye ko le fun ni.

4 E dide ki a si korin,
B‘a si ti fe tuka,
Ki ohun na ti a ti ko,
Le je fun rere wa.

5 Nje ‘gbati a ba korin tan,


T‘a ba si s‘ or‘ofe
K‘ ibukun Re le ba le wa.
Bi a ti nlo ‘le wa.
Amin.

554 L.M;
Ranti ojo isimi lati ya si mimo
Eks. 20:8.

1 mf L eyin ‘jo mefa t‘ o sise,


O simi ni ijo keje,
O pase fun wa k‘ a se be,
Ki a si pa OJO na mo.

2 A wa lati m‘ase na se,


Ninu ile Re yi loni,
Niwon ‘gbat‘ a mbe nihinyi,
Jek‘a mo p‘O mbe lodo wa.

3 p Bi ao ti s‘ iwe mimo Re,


Jek‘ ale ka pelu ‘rele,
K‘a le mo pe ‘Wo l‘o nsoro,
Ki ateti si eko Re

4 Tumo re fun wa fun‘ra Re


Alailogbon sa li awa,
Oro Re sa jinle pupo,
Oye wa ko si to fun u.

5 p Pelu awon oluko wa,


Fi Emi Mimo Re fun won,
Ki O ma ko won n‘itumo,
B‘o ti wu k‘ijinle na to.

6 Nigbat‘ a ba kuro nihin,


Jo masai pelu ona wa,
K‘a le ma se iranti Re
Titi ojo‘simi miran.
Amin.

5555 10.10.
Nigbana li eni-buburu ni wa, a si
mu eyi ti a fun si aiya re kuro.
Mat. 13:19.

1 mf Jesu Oba, a pari eko wa,


Ma jeki Esu sa je l‘okan wa‘

2 p Jesu Oba, a s‘ope l‘owo Re


T‘O ti fun wa li onje Orun je

3 Jesu Oba, ko s‘eko bi Tire.


Ihin Re dun pupo li eti wa

4 Jesu Oba, IWO li ao ma wo,


O ti ko wa be ninu Oro Re

5 p Jesu Oba, n‘ijade wa lo yi,


A be O k‘O dabobo gbogbo wa

6 Jesu Oba, ninu gbogb‘ ose yi,


p SO wa, si mu wa ri ose ti mbo
Amin.

556 C.M.
Inu mi dun nigbati nwon wifun
mi pe, E jeki a lo si ile Oluwa.
OD. 122:1.

1 Ile eko ojo ‘simi,


A! mo ti fe O to!
Inu mi dun mo daraya,
Lati yo ayo re.

2 Ile-eko ojo ‘simi


Ore re pa poju
T‘agba t‘ewe wa nkorin re,
A nse aferi re.

3 Ile-eko ‘simi
Jesu l‘o ti ko O;
Emi Mimo Olukoni,
L‘o si nje 'toju re.

4 Ile eko ojo‘simi


Awa ri eri gba,
P'Olorun Olodumare
F‘ibukun sori re.

5 Ile eko ojo‘simi


B‘orun nran l‘aranju,
Bi ojo su dudu lorun
Ninu re l‘emi o wa.

6 Ile-eko ojo ‘simi


Mo yo lati ri O,
‘Wo y‘o ha koja lori mi
Loni, l‘airi ‘bukun?
Amin

557 6.5.6.5.
Fi eti si ni, Oluso-agutan
Israeli OD. 80:1.

1 mf Olusagutan mi
Ma bo mi titi;
Olusagutan mi,
Ma to ese mi.

2 Di mi mu, si to mi,
Ni ona hiha,
B‘O ba wa lodo mi,
Emi ko sina.

3 Sin mi s‘ona orun,


Nijojojumo,
Mabusi ‘gbagbo mi,
Si mu mi fe O.

4 f K‘ ayo tabi ekun,


Ti odo Re wa;
K‘iye ainipekun,
Le je ayo mi.

5 Ma pese okan mi,


Ni ojojumo;
Si je k‘ Angeli Re,
Sin mi lo ile.
Amin.

558 7..7.7.7
Kiyesii, awon omo ni ini Oluwa:
omo inu si li ere re. OD. 127:3

1 mf Gb‘ adura wa Oluwa,


f F‘ awon omo t‘ O fun wa,
Pin won ninu ‘bukun Re.
Si fun won l‘ayo l‘orun

2 Jek‘ okan won Sunmo O,


Nigba won wa l‘omode
Je ki won f‘ogo Re han,
L‘akoko ‘gba ewe won.

3 p Fi eje Olugbala,
We okan won mo toto;
Je k‘a tun gbogbo won bi,
Ki won si le je Tire.

4 p Anu yi l‘a mbebe fun,


K‘ O si gbo adura wa;
IWO l‘agb‘ okan wa le,
Ni anu gb‘ adura wa.
Amin.

559 S.M.
A gbe awon Omo-Owo wa s‘Odo
re. Mat. 19:13.

1 Jesu pe omode,
O gbe won s‘aya Re;
O f‘owo Re gba won mora,
O si sure fun won.

2 p Jesu gb‘omode yi,


T‘a gbe wa s‘ile Re,
p Tikala Re se ni Tire,
K‘o dagba f‘ogo Re

3 p Gb‘ awon omode wa,


Ti won nwa waju Re,
pp Si pese f‘awon ti ko ni,
f Sure fun gbogbo wa.
Amin.

560 8.7.8.7
Bi awa ba se Omo, nje awa li
ajogun Rom. 8:17

1 Balogun! Olugbala wa,


Gb‘ omo wonyi t‘a bun O;
Se won ye fun ise Tiree,
Arole iye wonyi.

2 Arewa Baba wa orun,


Mu k‘awon wonyi jo O
N‘nu aworan Tire papa,
Lo won s‘agbala oke.

3 Se won l‘ agannigan mimo,


Omo-ogun t‘o lera;
Ki won fo itegun esu.
Ki won si segun aye.

4 K‘ oro Re dabi oguna,


L‘enu awon omo Re;
Ti y‘o jo ese l‘ ajorun,
K‘ ara ba le da sasa

5 Pa won mo fun ‘se ogo Re,


Ki won wa lailabawon;
KO won lati r‘agbelebu,
Lojojumo aye won.

6 Bukun ‘lana igbala yi,


Fun ire omo wonyi;
Gba won, to won, si ma SO won,
Nikeyin gb‘ okan won la.
Amin.

561 7.7.7.7.
IWO ki ise eru mo bikofe omo.
Gal. 4:7.

1f Ewe ti Oba orun


Korin didun b‘e ti nlo;
Korin ‘yin Olugbala,
Ologo n‘nu ise Re

2 A nlo sodo Olorun


L‘ona t‘awon Baba rin;
Won si nyo nisisiyi,
Ayo won l‘awa o ri.

3 cr Korin agbo kekere,


E o simi n‘ite Re;
Ib‘apese ‘joko yin,
Ibe si n‘Ijoba yin.

4 Woke, Omo imole


Ilu Sion wa lokan;
Ibe n‘ile wa titi,
Ibe l'a o r‘Oluwa.

5 Ma sa, e duro l‘ayo,


Ni eti ile ti yin;
Kristi Omo Baba nwi
Pe, Laifoya k‘a ma LO

6 mf Jesu, a nlo l‘ase Re,


A ko ‘hun gbogbo sile
IWO ma j‘ Amona wa
A o si ma ba O lo.
Amin.

562 6.6.6.6.
Oluwa, emi nfe ibujoko Re,
ibi ago Ola Re OD. 26:8.

1 f Olorun awa fe
Ile t‘ola Re wa;
Ayo ibugbe Re,
Ju gbogbo ayo lo

2 mf Ile adura ni,


Fun awon omo Re;
Jesu o wa nibe,
Lati gbo ebe wa.

3 Awa fe isun Re
Nibe l‘Emi mimo
‘Tu or‘-ofe jade
Gegebi t‘igba ni

4 Awa fe ase Re
Kil'o dun to laye?
Nib‘ awon oloto
Nri O ni ‘tosi won.

5 A fe Oro iye,
Ti nso t‘ alafia,
T‘itunu n‘nu ija
Atayo ti ki tan.

6 A fe korin anu,
T‘a nri gba l‘aye yi:
Sugbon awa fe mo
Orin ayo t‘Orun.

7 Jesu Oluwa wa,


Bu si ‘fe wa n‘ihin;
K‘a r‘ oju Re l‘orun
K‘a ba ‘won mimo sin.
Amin.

563 L.M.
Nibiti eni meji, tabi meta ba
ko ara won JO li oruko Mi, nibe
li Emi o wa li arin won. Mat. 18:20.

1 mf Jesu, ni b‘eni Re pade,


Nibe, won r‘ite anu Re,
Nibe, won wa O, won ri O
Ibikibi ni ‘le owo.

2 mf Ko s‘ogiri t‘o se O mo,


O ngbe inu onirele;
Won mu O wa! bi won ba wa,
‘Gba won nlo ‗le, won mu O lo.

3 mf Olus‘agutan eni Re,


SO anu Re ‘gbani d‘otun
cr SO adun oruko nla Re,
Fun okan ti nwa oju Re.

4 mf Je k‘a ripa adua nihin,


Lati so ‘gbagbo di lile
Lati gbe ife wa soke,
Lati gb‘orun ka ‘waju wa.

5 cr Oluwa‘WO wa nitosi,
N‘apa Re, de ‘ti Re sile;
Si orun, sokale kankan;
Se gbogbo okan ni Tire
Amin.

564 8.7.8.7.6.7.
Ojo ibukun yo si ro Esek. 34:26.

1 f Oluwa, mo gbo pe, Iwo


Nro ojo ‘bukun kiri;
Itunu fun okan are,
Ro ojo na s‘ori mi,
An‘ emi an‘emi
pp Ro ojo na s‘ori mi.

2 mf Ma koja, Baba Olore,


Bi ese mi tile po,
‘Wo le fi mi sile, sugbon
p Je k‘anu Re ba le mi
An‘ emi, an‘emi
Je k‘anu Re ba le mi.

3 mf Ma koja, mi, Olugbala,


Je k‘emi le ro mo O,
cr Emi nwa oju rere Re,
p Pe mi mo awon t‘O npe,
An‘ emi, an‘emi
Pe mi mo awon t‘O npe.

4 mf Ma koja mi, Emi mimo,


‘WO le laju afoju,
Eleri itoye Jesu,
p Soro ase na simi,
An‘ emi, an‘ emi
Soro ase na simi.

5 mp Mo ti sun fonfon nin‘ese,


Mo bi O ninu koja,
ff Aye ti de okan mi, jo,
p Tu mi, k‘O dariji mi,
An‘emi, an‘emi
Tu mi, k‘O dariji mi.

6 cr Ife Olorun, ti ki ye,


Eje Krist‘ iyebiye,
ff Ore-Ofe alaini won
di Gbe gbogbo re ga n‘nu mi
An‘ emi, an‘emi
Gbe gbogbo re ga n‘nu mi:

7 mp Ma koja mi, dariji mi,


Fa mi mora, Oluwa,
cr ‘Gba O nfi‘bukun felomi
Ma sai f‘ibukun fun mi,
An‘emi, an‘ emi
p Ma sai fi‘bukun fun mi.
Amin.

565 11.11.11.11.
IWO SO mi di aye gege bi
Oro Re- OD. 119:25.

1 mf Fun mi n‘iwa mimo; igbona okan,


Suru ninu iya; aro fun ese;
Igbagbo n‘nu Jesu! ki nmo ‘toju Re,
AyO n‘nu isin Re, emi adura.

2 f Fun mi l‘okan OPE, igbekele Krist‘


Itara f‘ogo Re; ‘reti n‘n‘ Oro Re,
p Ekun fun iya Re; ‘rora f‘ogbe Re;
p Irele n‘nu ‘danwo; Iyin fun ‘ranwo.

3 mf Fun mi n‘iwa funfun, fun mi n‘isegun,


We abawon mi nu, fa ‘fe mi s‘orun.
Mu mi ye ‘joba Re, ki nwulo fun O.
Ki nj‘ alabukunfun; ki ndabi Jesu .
Amin.

566 10.8.10.8. & Ref.


E ma ko gbogbo aniyan
nyin le e. I Pet. 5:7.

1 p So gbogbo ‘banuje re fun Jesu


Ati gbogbo aniyan re;
Dajudaju yio da O n‘ide,
On yio si tu O ninu
Mp SO won fun Jesu,
SO won fun Jesu,
So won fun Jesu,
On y‘o gbo;
Sa gbekele ki
O si gba A gbo;
On yio si tu O ninu.

2 mp So won fun Jesu Olugbala re


SO won k‘o si ri ‘gbala Re;
Mase se Jesu, mase d‘oju ti,
On yio si tu O ninu.

3 cr So won fun Jesu, On ni abo re,


LO si odo Re fun anu;
SO fun Jesu, gbagbo ‘WO O si ri
Ore-ofe ati ‘tunu.
Amin.

567 8.7.8.7.D.
Oluwa yio ma to o nigbagbogbo.
Isa. 58:11.

1 mf Oluso-agutan,to wa
Awa fe itoju Re
Fun wa ni ibukun t‘a nfe,
Si pese aye fun wa,
Jesu mimo, Jesu mimo
O ra wa, Tire ni wa )2ce

2 cr Tire ni wa; li wa s‘ore,


Ma se amona fun wa,
Gba agbo Re lowo ese.
Wa wa gbat‘ a ba sina
Jesu mimo, Jesu mimo
Gbo tiwa, gba t‘a mbebe)2ce

3 mp 'Wo ti leri lati gba wa


B‘a tile je elese;
Anu, ore, agbara Re
T o fun 'dande elese
Jesu mimo, Jesu mimo
Je ka tete ro mo O )2ce

4 mf Je k‘a tete wa oju Re,


Je k‘a tele se‘fe Re,
Oluwa at' Olugbala,
Fi 'fe Re kun okan wa.
Jesu mimo, Jesu mimo
Olufe, ma fe wa si. )2ce
Amin.

568 H.7.8.7.D.
Oro mi li enyin ise.
Jn. 15:14.
1 mp Ore wo l'a ni bi Jesu
Ti o ru ‘banuje wa;
Anfani wo l‘o PO bayi
Lati ma gbadura si?
Alafia pupo l‘a nsonu
A si ti je‘rora po,
mf N‘tori a ko nfi gbogbo kan
S‘adura niwaju Re.

2 mp Idanwo ha wa fun wa bi?


A ha ni wahala bi?
A ko gbodo SO reti nu,
Sa gbadura s‘Oluwa,
Ko s‘oloto ore bi Re;
Ti o le ba wa daro
mf Jesu ti mo ailera wa,
Sa gbadura s‘Oluwa.

3 cr Eru ha nwo wa l‘orun bi?


Aniyan ha po fun wa?
Olugbala je abo wa,
Sa gbadura s‘Oluwa;
Awon ore ha sa O ti,
Sa gbadura s‘Oluwa,
f Y‘o gbe o s‘oke l‘apa Re,
IWO y‘o si ni ‘tunu.
Amin.

569 8.8.8.8.D.
E ma gbadura li aisimi.
I Tes. 5:17.

1 mf Jesu Oluwa gbogbo wa,


T‘O wa bakanna titi lae
F‘eti si ‘gbe Om‘eyin Re,
Si ko wa b‘a ti ngb‘adura,
Fun wa li ebun adura,
Ji wa dide k‘a w‘oju Re.

2 di Ao le ro ero rere kan,


Ao le ni ife rere kan
Afi bi‘Wo t‘Oda aye
Mi agbara na s‘okan wa;
mf Gba na l‘a o k‘edun l‘emi
Re L‘ao fun O li ohun Tire.

3 di Jesu, f‘eti si aroye


Omo-eyin Re t‘a ndanwo
mp Fun wa l‘ohun ni t‘a ko ni,
Ran Olutunu Sokale;
Fi Emi adura fun wa,
Fi ajele Re s‘okan wa.

4 mp Fi Alagbawi na fun wa,


K‘o si fun wa li ara Re,
Ki ailera wa le dinku,
K‘aniyan elese le tan
K‘a le f‘okun fun ebe wa
K‘okan wa d‘ile adura.

5 mp Sokale l‘emi adura


S‘odo awa ti nw‘ona Re;
Ebun agbara adura,
Nikan la ntoro lowo Re;
Fi eyi ke wa; Oluwa;
Wo ki oduwa n‘iyoku.
Amin.

570 C.M.
Emi ki yio jeki O lo, biko sepe
O ba sure fun mi. Gen. 32:26.

1 mp Olus‘agutan, toju wa
Li ojo ibi yi,
Fun gbogbo omo-eyin Re
N‘ipa lati sona.

2 mp B‘igba idanwo wa ba pe
T‘iponju po fun wa,
Jek‘ emi wa simi le O
L‘adura aisimi.

3 mp F‘ore-ofe emi ebe


Fun wa nipa gbagbo
K‘a du titi a o r‘oju Re,
T‘ao si mo oko Re

4 mp Titi O fun wa l‘ara Re


Ati ife pipe,
K‘eyi je igbe gbogbo wa
Nki o jeki O lo

5 mf O ki O lo biko sepe
O s‘oko re fun mi;
K‘o f‘igbala Re bukun mi,
Si je ndabi Re.

6 mf Je ki nroju Re kedere
‘Gba m‘ba d‘ori-oke;
cr Nibi t‘ar‘ohun t‘a gbagbo,
f T‘adura di iyin.
Amin.

571 10.10.
O ye ki enia ma gbadura nigbagbogbo
laisimi ati lai sare Lk. 18:1.

1 mf Ma gbadura; Emi mbebe, n‘nu re,


Fun gbogbo aini re igba-gbogbo.

2 mp Ma gbadura; l‘abe eru ese,


Adura nri eje Jesu ti nsan.

3 Ma gbadura; b‘are tile mu O,


Adura ngbe wa s‘eba ‘te Baba.

4 cr Ma gbadura; n‘nu wahala aye,


Adura l‘o nfun okan n‘isimi.

5 f Ma gbadura; b‘ayo ba yi o ka,


cr Adura nlu harp o nkorin angel‘.

6 p Ma gbadura b‘awon t‘o feran ku,


cr Adura mba won mu omi iye.

7 di Gbogb‘ ohun aye y‘o b‘aye koja,


mf Adura wa titi; ma gbadura.
Amin.

572 LM
Nibe lemi O pade re, emi o si ba O
SORO lati oke ite anu wa. Eks. 25:22.

1 mf Ninu gbogbo iji ti nja,


Ninu gbogbo igbi ponju,
Abo kan mbe, ti o daju
p O wa l‘abe ite anu.

2 mf Ibi kan wa ti Jesu nda


Ororo ayo s‘ori wa;
O dun ju ibi gbogbo lo,
p Ite-anu t‘a f‘eje won.

3 f Ibi kan wa fun idapo;


Nibi ore npade ore;
L‘airi ‘ra nipa igbagbo,
p Nwon y‘ ite-anu kanna ka.

4 f A! nibo ni a ba sa si
Nigba ‘danwo at‘ iponju?
A ba se le bori esu
p Bo sepe ko si ‘te anu.

5 f A! bi idi l‘a fo sibe


B‘enipe aye ko si mo,
Orun wa pade okan wa,
p Ogo si bo ite-anu.
Amin.

573 7.6.7.6.D.
E ma gbadura laisimi. 1 Tes. 5:17.

1 mf Lo, l‘oro kutukutu,


Lo, ni osan gangan
Lo, ni igba asale,
Lo, ‘loganjo oru;
Lo t‘iwo t‘inu rere
Gbagbe ohun aye
p Si kunle n‘iyewu re,
Gbadura ni ‘koko.

2 mf Ranti awon t‘o fe o


At‘ awon t‘iwo fe
Awon t‘o korira re,
Si gbadura fun won;
Lehinna, toro ‘bukun,
Fun ‘wo tikalare,
Ninu adura re, ma
Pe oruko Jesu.

3 B‘ aye lati gbadura


Ni ‘koko ko ba si;
T‘okan re fe gbadura
‘Gbat‘ ore yi o ka,
‘Gbana, adura jeje,
Lati okan re wa
Y‘o de odo Olorun
Alanu, Olufe

4 f Ko si ayo kan l‘aye


T‘o si ju eyi lo
Nit‘ agbara t‘a fun wa
Lati ma gbadura;
p ‘Gbat‘inu re k‘o ba dun
Wole, k‘o gbadura,
cr Ninu ayo re gbogbo
Ranti or‘ofe Re
Amin.
574 C.M.
Oju Oluwa mbe lara awon olododo,
Eti Re si si igbe won. OD. 34:15.

1 mf Oju kan mbe ti ki togbe


Nigbat‘ ile ba su,
Eti kan si mbe ti k‘ise
'Gbati orun ba wo.

2 Apa kan mbe ti ko le re


‘Gba ‘pa eniyan pin;
Ife kan mbe ti ko le ku
‘Gba‘fe aye ba ku.

3 Oju na nwo awon Seraf!


Apa na d‘orun mu;
Eti na kun f‘orin angel‘,
Ife na ga l‘oke.

4 mf Ipa kan l‘eniyan le lo,


‘Gbat‘ ipa gbogbo pin,
Lati ri oju at‘apa
Ati ife nla na.

5 cr Ipa na ni adura wa
Ti nlo ‘waju ite;
T‘o nmi owo t‘o s‘aye ro
Lati mu ‘gbala wa.
Amin.

575 L.M.
E ma duro sinsin ninu Adura
igba pelu idupe. Kol. 4:2.

1 mf Ikose ti po to, t‘a nri,


Li ona wa s‘ite-anu?
Sibe, tani mo ‘yi adua
Ti ki y‘o fe ma wa nibe?

2 mf Adua ni ‘tu ‘ju ojo ka,


Ni gun ategun Jakobu;
Adua l‘agbara igbagbo,
Ni mu ibukun sokale.

3 mf Adura mu ki ija tan,


On ni ‘se ‘hamora Kristian
Satani gbon, nigbat‘ori
Elese lori ekun re.

4 mp Busi ‘gbagbo at‘ife wa,


K‘a le m‘ore Re, Oluwa,
K‘a jere eso adura,
Lat‘ inu isura Re wa

5 mf B‘oje‘daji edun okan wa


L‘o ngoke gege bi ebe
Orin ayo wa yoo ma je
―W‘ohun t‘Oluwa se fun mi"
Amin.

576 8.8.8.4.
Wakati adura. Ife. A. 3:1.

1 mf Olorun lat‘ ooro d‘ale,


Wakati wo l‘o dun pupo,
B‘eyi t‘o pe mi wa ‘do Re,
Fun adura?

2 Ibukun n‘itura oro


Ibukun si l‘oju ale;
‘Gbati mo f‘adura goke
Kuro l‘aye!

3 ‘Gba na ‘mole kan mo si mi


O dan ju 'mole orun lo
Iri ‘bukun l‘aye ko mo
T' odo Re wa.

4 ‗Gbana l‘agbara mi d‘otun,


‗Gbana l‘a f'ese mi ji mi,
‘Gbana l‘o f‘ireti orun
M'ara mi ya.

5 Enu ko le so ibukun
Ti mo nri f‘aini mi gbogbo
Agbara, itunu, ati
Alafia

6 Eru at' lyemeji tan,


Okan mi f‘orun se ile
p Omije ‘ronupiwada
L‘a nu kuro.

7 Titi un o de ‘le‘bukun na,


Ko s‘anfani to le dun bi
Ki nma tu okan mi fun O
Nin‘ adura!
Amin.

577 D.L.M.
Wakati adura. Ise A. 3:1.

1 f Wakati adura didun!


T‘o gbe mi lo kuro l‘aye,
Lo ‘waju ite Baba mi,
Ki nso gbogbo edun mi fun;
cr Nigba‘banuje at‘aro
Adua l‘abo fun okan mi;
Emi si bo lowo esu;
‘Gbati mo ba gb‘adua didun.

2 f Wakati adura didun,


Iye Re y‘o gbe ebe mi
Lo sod‘ Eni t‘O se ‘leri
Lati bukun okan adura,
B‘O ti ko mi ki nw‘oju Re,
Ki ngbekele, ki nsi gba gbo;
Un o ko gbogb‘ aniyan mi le
Ni akoko adua didun.

3 Wakati adura didun,


Je ki nma r‘itunu Re gba
Titi un o fi d‘oke Pisga
Ti un o r‘ile mi l‘ okere;
Uno bo ago ara sile,
Un o gba ere ainipekun,
f Un o korin bi mo ti nfo lo!
cr O digbose adua didun.
Amin.

578 s.m.
Igboiya lati wo inu ibi mimo nipase
Eje Jesu. Heb. 10:19.

1 mf Sa wo ite-anu,
Oro Re pe mi wa;
Nibe Jesu foju ‘re han
Lati gbo adura.

2 p Eje etutu ni
Ti a ti ta sile
Pese ebe t‘o le bori
F‘awon t‘o nt‘Olorun.

3 Bere ohun t‘o fe,


‘Wo ko le bere ju;
Eni t‘O t‘eje Re sile
Kini y‘o fi du o?

4 Ife Re le fun mi,


Ju bi mo ti fe lo;
A ma fun eni t‘o bere
Ju bi won ti n felo

5 Fun wa l‘aworan Re
At‘ oju-rere Re;
Je ki nle sin O nihinyi,
Ki mba le ba O gbe.
Amin

579 L.M.
Nitori nibe ni Oluwa gbe
pase ibukun. OD. 133:3.

1 f Pase ‘bukun Re t‘oke wa


Olorun, s‘ara Ijo yi;
mf Fi ife ti Baba wo wa
p ‘Gbat‘ a f‘eru gb‘oju soke. ‘

2 mf Pase ibukun Re, Jesu,


K‘a le se omo eyin Re;
Soro ipa s‘okan gbogbo,
p So f‘alailera, ‘tele mi.

3 mf Pase ‘bukun l‘akoko yi


Emi oto, kun ibi yi,
mf F‘agbara iwosan Re kun,
At‘ ore-ofe isoji.
Amin.

580 7.7.7.7.
Kini iwo nfe ti emi iba se
fun o. Lk. 18:41.

1 mf Mura ebe, okan mi,


Jesu nfe gb‘adura re;
O ti pe k‘o gbadura,
Nitorina yio gbo.

2 L‘odo Oba n‘iwo mbo,


Wa lopolopo ebe;
Be l‘ore-ofe Re po,
Ko s‘eni ti bere ju.

3 mp Mo t‘ibi eru bere;


Gba mi ni eru ese;
di Ki eje t‘O‘ta sile
We ebi okan mi nu.

4 S‘odo Re, mo wa ‘simi,


Oluwa, gba aya mi;
Nibe, ni ki O joko
Ma nikan joba nibe.

5 B‘eniyan ti nri ‗ra re,


Ni inu awojiji,
Be ni k‘O yo ‗s‘okan mi,
Ya aworan Re sibe

6 N‘irin ajo mi l‘aye,


K‘ ife Re ma tu mi n‘nu,
Bi Ore at‘ Oluso
Mu mi d‘opin irin mi.
Amin.

581 8.7.8.7.8.7.
Ki ore-ofe Oluwa wa Jesu Kristi
ki o wa pelu nyin. I Tes. 5:28.

1 mf Fi ibukun Re tu wa ka,
Fi ayo kun okan wa;
K‘olukuluku mo ‘fe Re
f K‘a l‘ayo n‘nu ore Re;
Tu wa lara tu wa l‘ara
La aginju aye ja.

2 f Ope at‘iyin l‘a nfun O


Fun ihinrere ayo;
mf Je ki eso igbala Re,
Po l‘okan at‘iwa wa;
cr Ki oju Re, ki oju Re
Ma ba wa gbe titi lo

3 p Nje n‘igbat‘aba sipe wa


Lati f‘aye yi sile
cr K‘ Angeli gbe wa lo s‘orun,
L‘ayo ni k‘a j‘ipe na;
f K‘a si joba, k‘a si joba
Pelu Kristi titi lae.
Amin.

582 8.7.8.7.D.
Olorun ore-ofe gbogbo ti o ti pe n yin
sinu ogo Re ti ko nipekun ninu
Kristi Jesu. I Pet. 5:10.

1 f Wa, iwo isun ibukun,


Mu mi korin ore Re;
Odo anu ti nsan titi
Bere orin ‘yin kikan;
Oluwa, ko mi l‘orin na
T‘ogun orun nko l‘oke
Je ki nroyin isura na
Ti ife Olporun mi

2 mf Nihin l‘a ran mi lowo de


Mo gbe Ebenezer ro
cr Mo nreti nipa anu Re
Ki ndede l‘alafia;
p L‘alejo ni Jesu wa mi,
‘Gba mo §sako lo l‘agbo
Lati yo mi ninu egbe
O feje Re s‘ etutu.

3 cr Nit or‘-ofe lojojumo


Ni ‘gbese mi si npo si;
K‘ ore-ofe yi ja ewon
Ti nse ‘dena okan mi,
p Ki nsako sa l‘okan mi nfe
Ki nko Jesu ti mo fe
cr Olugbala gba aya mi;
Mu ye f‘agbara orun.
Amin.

583 10.10.10.10.
Oluwa yio fi di alafia bu si i fun
awon enia Re. OD. 29:11.

1 f Olugbala, a tun fe f‘ohun kan


Yin oruko Re k‘a to tuka lo;
Ni ‘pari ‘sin, a dide lati yin;
p A o si kunle fun ibukun Re.

2 mp F‘alafia fun wa, b‘a ti nrele,


cr Jek‘a pari ojoyi pelu Re;
mf Pa aya wa mo, si so ete wa
T‘a fi pe oruko Re n‘ile yi.

3 mp F‘alafia fun wa l‘oru oni;


cr SO okunkun re d‘imole fun wa,
Ninu ewu, yo awa Omo Re,
mf Okun on ‘mole j‘okanna fun O.

4 mp L‘alafia fun wa loj‘ aye wa,


cr Re wa l‘ekun k‘O si gbe wa ni ‘ja,
mf Leyin gbogbo ijagun aye yi,
p Pe wa, Baba, s‘orun alafia.
Amin.

584 8.7.8.7.D.
Ore ofe Jesu Kristi Oluwa.
IIKor. 13:14.

1 f K ‘ore ofe Krist‘ Oluwa,


Ife Baba ail‘opin,
Oju rere Emi mimo,
K‘o t‘oke ba s‘ori wa;
f Bayi l‘a le wa n‘irepo
Awa ati Oluwa;
K‘a si le ni ‘dapo didun,
At‘ayo t‘aye ko ni.
Amin.

585 L.M.
Nigbana ni O sore-ofe fun un,
O si wipe, Gbaa kuro ninu lilo sinu iho,
emi ti ri irapada! Jobu 33:24.

1 p Bi mo ti kunle, Oluwa,
Ti mo nbe f‘anu l‘odo Re,
cr Wo t‘Ore ‘lese ti nku lo
Si tori Re gb‘adura mi.

2 p Ma ro ‘tiju at‘ebi mi,


At‘ aimoye abawon mi,
cr Rot‘ejeti Jesu ta‘le
Fun ‘dariji on iye mi.

3 mf Ranti bi mo ti je Tire,
p Ti mo je eda owo Re;
Ro b‘okan mi ti fa s‘ese
Bi ‘danwo si ti yi mi ka.

4 mf A! ronu Oro mimo Re,


Ati gbogbo ileri Re,
Pe, WO O gbo adua titi
Ogo Re ni lati dasi.

5 p A! ma ro ti ‘yemeji mi,
Ati ailo or‘-ofe Re;
Ro ti omije Jesu mi,
Si fi ‘toye Re di t‘emi.

6 mf Oju on eti Re ko se,


Agbara Re ko le ye lae
JO wo mi, okan mi wuwo,
p Da mi si, k‘O ran mi lowo
Amin.

586 C.M
Ore-Ofe ki o wa pelu nyin.
II Tim. 4:22.

1 mf F‘ore-ofe Re ba wa gbe,
Jesu Olugbala
Ki eni arekereke,
K‘o ma le kolu wa.

2 cr F‘ oro mimo Re ba wa gbe


Olurapada wa
K‘a ri igbala on iye,
L‘ohun bi nihin yi.

3 Fi imole ba wa gbe
‘WO imole aye,
Jek‘ oro Re s‘amona wa
Ma si jek‘a subu.

4 mf Fi‘bukun Tire bawa gbe


Oluwa, Oloro;
Fi ebun orun rere Re
Bu si igbagbo wa.

5 Fi‘pamo Tire bawa gbe,


IWO Alagbara;
K‘a ma gbe ara le aye,
K‘a ma yen‘ ipo wa.

6 f Fi‘fe mimo Re bawa gbe,


Olorun Olore;
Ran wa lowo ninu ponju,
Mu wa duro ti O.
Amin.

587 8.5.8.5. & Ref.


Enikeni ti o ba pe oruko Oluwa
li a o gbala. Joe. 2:32.

1f Ma koja mi, Olugbala


Gbo adura mi;
‘Gbat‘ IWO ba np‘ elomlran,
di Mase koja mi.
Jesu, Jesu, gbo adura mi
‘Gbat‘ IWO BA np'elomiran,
Mase koju mi.

2 p N‘ite anu, Je k‘emi ri


Itunu didun,
p T‘edun t‘edun ni mo wole
Jo, ran mi lowo
3 mf N‘igbekele itoye Re
L‘em‘ o w‘oju Re;
p Wo ‘banuje okan mi san,
F‘ife Re gba mi.

4 mf ‘Wo orisun itunu mi,


Ju ‘ye fun mi lo,
Tani mo ni l‘aye lorun
Bikose iwo?
Amin.

588 L.M.
O ti ku fun gbogbo won, pe ki
awon ti o wa laye ki o ma si pe
wa laye fun ara won mo.
IIKor. 5:15.

1 mf Emi ko le saini ife


Si Eleda mi t‘O fe mi
Ni fifi emi Re lele
Ki emi elese le ye.

2 mp Bi nko ba fe Oluwa mi
Emi y‘o je alaimore;
p Iku Re y‘O ha jasan bi
Lori gbogbo ailera mi?

3 cr Oluwa jo fun mi n‘ife


Ki nle ma feran Re titi
Ojo aye mi y‘o d‘ opin,
Ti uno fi wo ‘nu ogo Re.

4 mf Jesu, Ore loto l‘O je,


Anu Re si duro laelae
Fun awon t‘on se ife Re
Ni pipe n‘nu iwa mimo.

5 f Jesu t‘O pa oro iku,


T‘O si pa ise esu run;
T‘ ese ko nipa l‘ ori mi
Je ki nle ma se ‘fe Re!
Amin.

589 7.7 7.7.D.


Teti sile si ebe awon enia Re:
ti nwon ba gbadura ki O si gbo
li orun; gbo, ki O si dariji.
I.A. Oba 8:30.
1 mp Jesu, ‘Wo Od‘agutan,
Ti O fara da ‘rora,
‘Wo t‘ O se ‘fe Baba Re
Ni fifi ese wa ji;
Awa ntoro anu Re
Ninu ebi ese wa;
Mu wa de ile ayo,
Ni ‘kehin, k‘a ba O gbe.

2 cr Ni ‘gba idamu aye,


Ma j‘Oluran lowo wa,
YO wa ninu idanwo
Ati l‘OWO ota wa;
Je k‘a mo riri ‘ku Re
Lori ‘gi agbelebu,
‘Gbagbogbo, je k‘ okan wa
Ma ranti iya t‘O je

3 mf Mu ki ife Re wa n‘nu
Gbogbo okan ti nsako
Mu Won mo adun ati
Iye ati ajinde
T‘iku Re mu wa fun won,
Tobe, nikehin ki Won
Ba le je alajopin
Ijoba ayeraye.
Amin.

590 10.10.10.10.
Bi O se ti emi, emi o kepe Olorun,
yio si gba mi. OD. 55:16.

1 mp Baba Orun mo na ‘wo mi si O;


Iranlowo miran emi ko mo;
IWO t‘O fewa bole bi aso
Fi ibukun Tire WO mi l‘ewu.

2 Olori Ijo orun on aye,


Fi Emi Mimo Tire tun mi da;
Lo ero, okan ati emi mi,
K‘emi le sise iwa saye mi.

3 cr Olorun Eleda gbogbo aye,


Jeki nwa O, ki nri O, ki nfe O,
Ki nfe, ki n huwa ‘fe si gbogb‘ eniyan
Ki nsi fiwa jo O n‘ise anu.

4 mf Isun ibukun, ife at‘ayo,


Bi orun n‘ijoba Re mu mi ran;
Ati lati aye yi lo k‘emi
L‘ayo at‘ ibukun orun rere.
Amin.

591 C.M.
Emi o gbe oju mi si ori oke wonni
nibiti iranlowo mi ti nwa. OD. 121:1.

1 mp Ran wa lowo, Oluwa wa,


Li akoko aini;
L‘ero, l‘oro ati n‘ise,
Li ojo wa gbogbo.

2 p Nigbati irobinuje
Mu k‘okan wa gbogbe,
T‘okan wa si tutu si O
Jowo, ran wa lowo

3 mf Mu ki igbagbo wa po si,
Nipa adura wa;
B‘igbagbo wa ba ti po to,
Be ni a o ri gba to.

4 B‘awa‘do Re bi alejo,
T‘a wole, t‘antoro.
Erun ori tabili Re,
Iba eyini to.

5 mf Sugbon, Oluwa alanu,


O kio s‘aifun wa;
Erun ori tabili Re
J‘ayo, ‘mole iye.

6 cr Ran wa lowo lat‘ oke wa,


Ao ni ‘ranwo miran;
Ran wa lowo k‘a je Tire
L‘ aye ati l‘orun.
Amin.

592 7.7.7.7.D.
Oluwa, emi ko gbe okan mi ga,
beni oju mi ko gbe soke. OD. 131:1,

1 mp Jesu, nigbat‘ a wole,


Ni ‘teriba, lese Re;
A fere ma le w‘oke
F‘ekun ‘ronupiwada,
p A wo gbogbo ‘rora Re
T‘O je laye n‘tori wa,
Siju anu Re wo wa,
Gbo adura ebe wa.
2 cr Ranti igba ewe Re,
Igba aini at‘ ekun
Igba awe at‘ ise
Li aginju aye yi,
mp Ranti ‘gba ti Esu nfe
F‘arekereke mu O,
F‘oju rere Re wo wa,
Gbo adura ebe wa.

3 pp Wo ekun Re kikoro
Lori oku Lazaru;
Wo omije Re t‘o san,
Lori Jerusalemu,
p Wo edun t‘O fi so pe;
Odale mbe l‘agbo Re;
Lati ‘bugbe Re orun
Gbo adura ebe wa.

4 p Ranti ‘gba t‘eru ba O


Ati ‗waya-ija Re,
Ranti ewu esin ni,
Ogbe at‘ade egun;
Ranti okunkun t‘o su,
‘Gbat‘ O fara Re rubo,
Fetisi irahun wa,
Gbo adura ebe wa.

5 p Ranti oro ikeyin,


At‘ edidi t‘a fi se
Iboji, t‘okunkun re
Ko le se Oluwa mo.
mp Olorun alagbara,
Ti o goke lo s‘orun,
Jo fetisi igbe wa,
Si gb‘adura ebe wa!
Amin.
593 S.M.
Wo odagutan Olorun. Jn. 1:36.

1 mp IWO Od‘-agutan,
T‘o ta ‘ je Re fun wa,
T‘o mu wa jade ni Egypt;
TO awon eni Re.

2 cr Angel‘ ore-ofe
Jewo agbara Re;
Wa, be awon ayanfe Re,
Ni ibudo Israel‘.
3 mf F‘imole Re to wa,
Ja ona aginju;
Je awo-sanma li osan
Ati ina l‘oru.

4 mf Fi ibukun orun
Gb‘emi ara wa ro;
Si rojo manna ife Re
Sori awon Tire.
Amin.

594 8.8.6.D.
E ji iji ododo, ki e ma si dese.
IKor. 15:34.

1 cr Olorun awamaridi
Ti ‘fe Re nsi mi bo pele
Lat‘ igba ewe mi,
JO, jeki nri ‘nu okan mi
Ki nmo bi m‘ba ni ‘dalare
Nipa or‘-ofe Re

2 di B‘oba se pe mo m‘eru Re
Ti mo si f‘okan oto je
Ipe atoke wa,
Busi or‘-ofe t‘O fun mi,
Si jek‘ okan mi mo adun
Ifiji ife Re

3 Nki o wa laini ife Re


Laini ‘reti n‘nu Oro Re,
Laini imo ‘fiji;
Baba, nki o tan ‘ra mi je,
Ki ns‘ alaini Eleri na
Ti s‘apere Orun.

4 cr B‘Eleri na ba ngbe n‘nu mi


Ki o ha SO t‘ilaja Re
T‘ase nipa Jesu?
Un o fi igbagbo sunmo O,
Un o f‘igboya ke pe, Baba!
Un o mo 'rami n‘Tire.

5 mp Ohunkohun t‘o le dena,


Idariji ‘fe Re si mi,
Ki ogo Re letan;
Jeki okan mi gba O gbo,
Fi gbogbo ese mi ji mi,
Si ko gbogbo won lo
6 mf Baba, f‘Omo Re han n‘nu mi
Si jeki okan mi le mo
B‘anu Re ti PO to;
F‘asiri ife Re han mi,
Ma gbe ‘nu okan mi titi
Nipa Emi Mimo.
Amin.

595 S.M.
Oluwa, fi eti si mi.
OD. 143:1.

1 mf Jesu, gb‘adura mi,


Fetisi igbe mi;
JO ranti Oro oto Re,
Si f or‘-ofe dahun.

2 cr Mase se idajo
Emi iranse Re;
N‘tori ko si alaye kan
T‘ o pe li oju Re.

3 mp Mote wo mi soke
Siha ‘bi mimo Re;
Okan mi npongbe, b‘asale,
Fun ‘tura ore Re.

4 di Oluwa, jo yara,
Gb‘okan are mi la!
Ma m‘oju kuro lara mi;
Emi dabi oku.

5 cr Igbagbo mi nfe ri
Imole anu Re;
JO jeki nrin niwaju Re
Mo gb‘okan mi si O.

6 mp Jek‘ Emi Re to mi
Si ona ododo;
Oluwa, n‘tori oko Re,
Gbe mi leke ibi.
Amin.

596 7.7.7.D.
Oluwa ni ipin mi nitorina ni emi se
ni ireti ninu Re. Jer. 3:24.

1 f Jesu, Olus‘-agutan,
Sanu aiba l‘okan mi;
Ma to mi, si pa mi mo,
Tit‘ ife Re se mi pe;
So mi di yiye koro,
Jek‘ igbagbo mi daju.

2 mp Nko le duro pe titi


Nigbagbo ni mo nsipo;
cr Sugbpn O wa bakanna,
L‘ana, l‘oni, titi lae;
f Fun mi n‘iduro-sinsin,
F‘or‘-ofe m‘okan mi le.

3 f Jek‘ igbagbp gbe mi ro,


Larin wahala aye;
Jeki ireti mimo
Se ‘dakoro okan mi
Se mi pe n‘ife mimo,
Ki nle je Tire titi.
Amin.

597 10.11.11.11.
Ninu ohun gbogbo ki O le ni ipo
ti o ga julo. kol. 1:18.

1 f Je iriran okan mi, Oluwa


Si je ohun rere gbogbo fun mi, Krist‘
mf Losan, loru je ero mi to dara,
Ki O si je ‘mole mi nigbagbogbo.

2 f Je oye mi, Oro otito mi;


Wa pelu mi, lai at‘emi pelu Re;
mf Je Baba fun mi, k‘emi je omo Re;
Ma gbe ‘nu mi, k‘a si je okansoso.

3 f Je abo mi, ida fun ija na;


Je ihamora ati agbara mi
mf Je ile agbara, abo okan mi;
To mi s‘on‘ orun, Alagbara julo,

4 f Nko lepa oro tabi ‘yin eda,


Je ipin mi nisiyi ati laelae;
mf Wa, ko si je ekini n‘nu okan mi;
Oluwa orun, IWO n‘isura mi.

5 f Oba giga orun, ‘mole orun,


JO fun mi layo Re lehin isegun,
mf Okan Mimo julo, joba ninu mi,
Je ‘riran okan mi, Alase eda.
Amin.

598
Fa mi, awa o sare to O.
O. Sol. 1:4.

1 mf Jesu ‘Wo ni t‘emi laelae


Oju gbogbo Ore lo;
cr Ni gbogbo irin-ajo mi
A! mba le fara mo O.
mp Sunmo O, sunmo O,
Sunmo O. sunmo O,
cr Ni gbogbo irin-ajo mi
A! mba le faramo O.

2 mf K‘ise fun oro aye yi


Ni mo se ngbadura yi;
cr Tayo tayo ni un o jiya
Bi mba sa le sunmo O
mp Sunmo O. sunmo O.
Sunmo O, sunmo O
cr Tayo tayo ni un o jiya
Bi mba sa le sunmo O.

3 mf ‘Gbat‘ ajo mi ba si dopin


Mu mi gunle sodo Re.
cr Si ilekun ayeraye
Ki nsunmo O titi lae
mp Sunmo O, sunmo O
Sunmo O, sunmo O,
cr Si ilekun ayeraye
Ki nsunmo O titi lae.
Amin.

599 8.7.8.7.D
Ki Olorun ki o sanu fun wa ki O
si busi fun wa. OD. 67:1.

1 f Baba wa, Eleda orun


Gbo ti wa l‘akoko yi;
Fi ore ofe Re kun wa
K‘a le j‘omo eyin Re.
mf Bukun wa, Baba, a mbe O
Dahun ebe wa loni,
Mase je k‘awa lo lofo,
F‘ ire kari wa, Baba.

2 cr Awon t‘o wa O n‘gb‘aye Re


Enikan, ko lo lofo;
B‘aini gbogbo won ti po to,
L‘O si bukun fun won to,

3 cr Ikunle wa j‘okan soso


Sugbon ebe wa yato;
Alailera nfe iwosan,
Alaini ntoro ‘bukun.

4 Fi ‘dahun ‘bere wa fun wa


B‘ a ti nw‘oju Re loni;
Ki gbogbo wa f‘ayo wipe,
― A ti ri idahun gba. ‘ ‘
Amin.

600 7.7.77.
Emi kigbepe O, Oluwa. OD. 30:8.

1 mf Wa, Jesu fi ara han,


Wa, je k‘okan wa mo O'
Wa, mu gbogb‘ okan gbona,
Wa, bukun wa k‘a to lo.

2 Wa, f‘aya wa n‘isimi,


Wa, k‘a d‘alabukunfun;
Wa, soro alafia,
Wa, busi igbagbo wa.

3 f Wa, le‘siyemeji lo,


Wa, ko wa b‘a'ti bebe;
Wa, fun okan wa n‘ife,
Wa, fa okan wa soke.

4 f Wa, so f‘okan wa k‘o yo,


Wa, wipe ―‘Wo ni mo yan;‖
Wa, p‘awon agbo Re mo,
Wa, sure f‘agutan Re.
Amin.

601 C.M.
E jeki a fi gboiya wa si ibi ite ore-ofe
ki a le ri anu gba. Heb. 4:16.

1 mp Ite anu! e je k‘a lo


Lati gba adura;
Olorun ‘fe y‘o sanu fun
Awon t‘o nsin nibe.

2 mp Ite anu! a, n‘ite na


L‘ekun wa ti nkunle;
Olorun si nro ‘jo 'bukun
Nigba kugba t‘a lo.

3 mf ‘Te anu! eyin mimo ye,


Ite na si sile;
Fi edun yin han Olorun,
Si wa ‘di ife Re

4 A ko le sai fe‘te anu,


Niwon bi a ti wa,
p Ati onigbowo, titi
Iku y‘o pa wa da.

5 mf ‘Gbana oju Jesu yoo tan


‘Mole y‘ite na ka,
A ki o si mo aini mo,
A k‘y‘o wa‘te anu.
Amin.

602 11.10.11.10.
Nitori ti awa gbekele Olorun alaye.
I Tim. 4:10.

1 mf L‘odo Re sibe nigbat‘ ojumo mo,


Ti awon eye ji ti kuku lo;
Re koja t‘orun ni didan imole,
Idaloju pe, ―O wa lodo mi.‖

2 p Nigbati are mu okan mi togbe,


O ko ‘ju si O ninu adura;
Orun na, ti dun to labe iji Re,
Sugbon k‘a ji k‘a ri O dun julo.

3 mf Beni, yoo ri l‘owuro ikeyin ni,


Ti okan ji, ti kuku aye lo;
Gbana ninu ewa t‘o ta t‘orun yo
Ero, ―mo wa pelu re yoo soji.
Amin.

603 C.M.
IWO ni ki o se ibujoko apata mi.
OD. 71:3.

1 Oluwa, ‘WO ki o si gba,


Eni osi b‘emi,
K‘emi le sunmo ite Re.
Ki nke Aba, Baba?
2 Jesu, jowo fi oro Re
S‘okunkun mi d‘osan;
Ki gbogbo ayo tun pada,
Ti mo f‘ese gbon nu.

3 Oluwa mo fiyanu sin,


Ore Re tobi ju:
Pa mi mo ninu ife Re,
K‘emi ma d‘ese mo
Amin.

604 C.M.
Omo mi, fi okan re fun mi.
Owe 23:26.

1 mf Gb‘ okan mi gege b‘o ti ri,


Te Ite Re sibe;
Ki nle fe o ju aye lo,
Ki nwa fun O nikan.

2 Pari ‘se Re Oluwa mi,


Mu mi je oloto;
K‘emi le gbohun Re, Jesu,
Ti o kun fun ife.

3 Ohun ti nko mi n‘ife Re,


Ti nso‘hun ti mba se;
Ti ndoju ti mi, nigba nko
Ba topa ona Re.

4 Em‘ iba ma ni eko yi,


T‘o nti odo Re wa;
Ki nko ‘teriba s‘ohun Re,
At‘ oro isoye.
Amin.

605 L.M.
Oluwa kiyesi aroye mi.
OD. 5:1.

1 f Oluwa, gbo aroye mi,


Gbo adura ikoko mi;
Lodo Re nikan, Oba mi,
L‘emi o ma iranwo.

2 mf L‘oro Iwo o gbohun mi;


L‘afemojumo ojo na;
Ni odo Re l‘emi o wo,
Si O l‘emi o gbadura.
3 Sugbon nigb‘ ore-ofe Re
Ba mu mi de agbala Re.
Odo Re l‘em‘ o teju mo,
Nibe un o sin O n‘irele

4 f Je k‘awon t‘o gbekele O,


ff L‘ohun rara wi ayo won:
Je k‘awon t‘Iwo pamo yo,
Awon t‘o fe oruko Re.

5 f Si olododo l‘Oluwa
O na owo ibukun Re;
Ojurere Re l‘eniyan Re
Yio si fi se asa won.
Amin.

606 6.4.6.4.6.6.6.4.
Oluwa si nlo niwaju won.
Eks. 13:21

1 mp Fun mi n‘iwa pele,


Okan tutu;
Ifarabale bi T‘Oluwa mi;
p Irele on suru
At‘opo iyponu,
cr Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

2 mp Fun mi n‘itelorun
N‘ipo k‘ipo;
Ko le re ‘le ju yi
T‘ a bi Jesu.
p Fun mi n‘itunu Re,
At‘iranlowo Re.
cr Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

3 mp Fun mi ni itara
S‘ipa Tire;
Aniyan at‘ife
S‘ohun t‘orun;
p Fun mi n‘iwa mimo,
Ikorira ese
cr Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

4 mp Fun mi ni igbagbo;
At‘ireti;
Fun mi l‘ayo ‘gbala
Ninu Jesu;
f F‘emi iye fun mi,
Fun mi l‘ade ogo,
ff ‘Gba ti mo ba jinde
Ki njo Jesu.
Amin.

607 6.6.6.6.8.8.
Emi o makorin iyin si
Olorun mi. OD. 104:33.

1 Si ohun ti a gbin,
Se iri ‘bukun Re;
Agbara ni Tire,
Lati mu k‘o dagba:
Je ki ‘kore k‘opo sii,
Iyin a je Tire nikan.
Amin.

608 7s.
Enyin o si saferi mi e o si ri mi
ti e ba fi okan nyin wa mi.
Jer. 29:13.

1 mf Oluwa, a wa ‘do Re
L‘ese Re l‘a kunle si;
A! ma kegan ebe wa,
Ao wa O lasan bi?

2 L‘ona ti O yan fun wa,


L‘a nwa O lowolowo;
Oluwa, a ki o lo,
Titi ‘Wo o bukun wa.

3 Ranse lat‘oro Re wa
Ti o fi ayo fun wa
Je ki emi Re k‘o fun
Okan wa ni igbala.

4 Je k‘a wa, k‘asi ri O,


Ni Olorun Olore;
W‘alaisan da ‘gbekun si
Ki gbogbo wa yo si O.
Amin.

609 S.M
O ti to wakati nisisiyi fun nyin
latiji loju orun. Rom. 13:11.

1 f Olurapada mi,
Gb‘emi mi n‘n‘ orun yi
SO fun mi nisiyi Ji! Ji!
Kristi yo wo O san.

2 f Gbe OWO Re le mi;


Ji mi nisisiyi,
Je ki oye ye mi daju
B‘agbara Re ti to.

3 mp Je ki nle ke pe O.
K‘emi si ma sora,
Ki n ma ba bo sinu ‘danwo,
K‘asa mi ma sonu.

4 Je ki nmura sile
De ikolu ota,
Ki nwa n‘iduro gangan lae,
K'emi si ma wo O.

5 di 'Wo ri ailera mi;


cr Krist ‘ je agbara mi,
mf 'Ranlowo mi ninu 'ponju,
Abo ni'odi mi.

6 Je ki ngb'okan le O,
cr Je ibugbe fun mi,
f Iwo apata, asa mi,
At‘Olugbala mi.

7 f Nko le gba ‘ra mi la,


Nko le pa ra mi mo;
cr Agbara mi t‘owo Re wa,
mf ‗Wo eni ti ki sun.

8 mp Iwo ni kan soso


Ni mo t‘emi mi fun;
cr Jesu, fe mi b‘awon Tire;
f Si fe mi de opin.
Amin.

610 13.13.12.12. & Ref.


Nitori Emi ni Oluwa ti o mu
o larada. Eks. 15:36

1 f Gbo iro ese Jesu, O nkoja lo bayi,


O ni ‗tura f‘agbogbe, O ns‘awotan arun;
Bo ti so f‘alaisan ni leti adagun,
O nwi be nisisiyi, ―O nfe ‗wosan bi?‖
Mf O nfe ‗wosan bi?
O nfe ‗wosan bi?
P Wa, alailera, wa;
Wa, elese wa;
F Wo omi iye ti nsan,
Omi iwenumo,
Wo inu re, iwo yo si ‗wosan

2 f Ohun Olugbala ni, ipe anu Re,


Mu igbala ofe wa fun gbogbo eniyan;
O npe gbogbo okan ti eru ese npa,
O nfi ife bere pe: ―O nfe ‗wosan bi?‖

3 mf Ara nni o, eru ese nwo o l‘ORUN,


O ko ha le wonu omi ni bi o ti nru?
F Wo Oluwa nduro lati fun o l‘okun,
O si nfi ‗fe bere pe: ―O nfe ‗wosan bi?‖

4 mp Ran wa lowo Jesu ka gbeke l‘oro Re,


Je ki emi iwosan be le wa loni yi,
We abawon ese nu, si s‘akoso wa,
So f‘okan to nwa o pe: ―O nfe ‗wosan
bi?‖

611 L.M.
Won si to wa lati iha gbogbo wa. Mk. 1:45

1p Jesu, ‗Wo Onisegun nla


T'olokunrun nf‘ailera mo
Nigba aisan at‘irora
O se dida ara fun won

2p Afoju, aro, alaisan,


Won ko sai ri ‘toju Re gba,
‘Torina, awa s‘odo Re,
A ntoro anu Re nikan

3 p Irora ti ‘WO la koja,


Jesu, ‘WO le se ‘wosan re
Awon to nw‘onisegun nla
Jo masai se iwosan won.

4 p Oluwa, je ki irora
M‘alaisan tubo sun mo O;
Ki owo egba Re kokan
Fa asako sunm‘odo Re.

5 cr Se ‘wosan okan to gb‘ogbe


Si gba okan ese wa la;
cr F‘OPO ilera Re fun wa,
Ki le ma yin O titi lae.
Amin.
612 7.7.7.7.
Nigbati O ri opo eniyan, anu
won se E. Mat. 9:36.

1 mf ‗Gbati Jesu wa l‘aye,


O nsore, O si nsanu;
F Ko s‘eni t‘o kere ju
Ti ko sai f‘anu han fun.

2 mf Awon afoju nyika


Ayaro at‘aditi;
F Gbogbo won li O nwosan,
O si nbukun gbogbo won.

3 mf O le wo adete san
O f‘onje be egberun;
Iji okun ngbo Tire
Oro Re ji oku n‘de.

4 mf Awon elese yi ka;


Won nyo lati gb‘oro Re
Awon ota Re papa
L‘oro Re ya lenu ju

5 mf F‘ife Re han mi, Jesu,


F‘Ore-Ofe Re kun mi;
F‘owo iwosan to mi,
Sure fun mi, bukun mi.

613 10.6.10.6. & Ref.


Nitori O wi ninu ara repe, bi
mo ba sa le fi owo kan aso Re,
ara mi o da. Mat. 9:21.

1 Iseti Re lo f‘owo kan


Bo ti sunmo ‘do Re;
mf Larin opo eniyan to pejo
O si r‘iwosan gba.
f Dide, f‘owokan aso Re;
IWO yo r‘iwosan,
Ase iwosan Re sibe
Yo mu o lara le.

2 p Teruteru l‘obinrin na wole,


Olugbala ti de;
mf Ase iwosan jade lara Re
O si mu larada.

3 cr Jesu yipada, O soro ‘tunu:


f Ma lo pelu ‘gbagbo;
Alafia de sin‘ obinrin na,
Ayo kun okan re.
Amin.

614 D.C.M.
Nse dida ara gbogbo awon ti esu
si n pon loju. Ise A. 10:38.

1 mf Apa Re li ojo wonni


Nwosan, o si ngbala;
O nsegun iku at‘aisan,
Ati isa-oku;
cr Awon afoju nto o wa,
Aro at‘amukun;
Adete, alarun egba:
Gbogbo won r‘iwosan.

2 mf Ase iwosan ntu jade,


Ti nmu won larada;
Omode at‘agbalagba,
Won nri idasile;
cr Sunmo wa lati bukun wa
Bi ti ojo ‘gbani;
Egbegberun n f‘owo kan O.
Won nfo soke fayo.

3 mf IWO je Onisegun wa,


Jesu Oba iye;
Tun wa soji, si bukun wa
Nip‘ agbara nla Re;
cr Fi ogbon orun Re kun wa,
SO ope d‘ologbon;
Ki gbogbo wa gbohun s‘oke
Lati yin O titi.
Amin.

615 8.7.8.7.D.
Jesu Kristi okan na ni li ana
ati li oni, ati titi lae. Heb. 13:8.

1 mf Jesu, okan na ni titi


Bi O ti wa nigbani:
Lasan li orun apadi
N dojuko agbara Re,
L‘okan awon eniyan Re,
Onjoba titi d‘oni:
f Tire ni gbogbo agbara,
O nfa ide ese ja.
2 mf Jesu, okan na ni titi,
O nwosan titi d‘oni,
Ko s‘alaisan to le pada
Lai fun n‘imularada;
O nwo aisan to buruju,
O sa mo ailera wa,
f O le ru ‘banuje wa lo
Bi a ba ko won to wa.
Jesu, okan na ni titi,

3 mf Ka sa ma gbe inu Re;


Ko sohun ti o le ya wa
Ninu ife Oluwa;
O le ko aniyan wa lo,
O si le tu wa ninu;
Olugbala to sowon ju,
Ko s‘oruko bi Tire.
Amin.

616 C.M.
Jesu Kristi okan na li ana, ati
li oni, ati titi lae. Heb. 13:8.

1 cr Jesu, p‘ase iwosan Re


Mbe bakanna d‘oni,
Jek‘agbara oruko Re
Wo ailera mi san.

2 cr B‘Iwo ba nse ore sibe


Fun awon alaini
Se ise ‘yanu Re fun mi
Ki nle f‘iyin Re han.

3 cr Jesu, mo kepe O loni,


Tun s‘ise-‘yanu Re;
F‘anu wo emi adete.
Mo wole lese Re

4 mp Eti mi di si ofin Re
Jesu, si mi l‘eti,
Pase k‘owo mi riro na
Ki ngbe soke si O.

5 cr Bi aro l‘eti adagun,


Jeki nri okun gba;
Un o fo soke bi agbonrin
Uno fo tayo-tayo.

6 Mo j‘afoju lat‘inu wa,


Okan mi sokunkun;
Nko le ri ife Olorun
Nko mo riri ese

7 mf Mo gbo pe IWO nkoja lo,


Jo mas‘aisunmo mi!
f Jesu, Iwo Omo Dafid‘,
Sanu, gbo ebe mi!

8 Wo, mo duro de O lona,


IWO ‘mole orun;
Pase ka fa mi wa, SO pe,
Elese, la ‘ju re.
Amin.

617 L.M.
Emi ko wa ipe awon olododo,
bikose awon elese si ironupiwada.
Lk. 5:32.

1 mf ‘ Wo t‘opo eniyan wa woto,


Lati gboro iyanu Re
cr Jek‘elese sunmo ‘do Re,
Si f‘oju-re tewogba wa.

2 mf ‘WO SO p‘eni t‘ara re le


Ko wa onisegun rara;
Emi ko san, mo nfe ‗wosan,
Mo nfe agbara ‗gbala Re

3 Agbara, oto, ife Re,


Bakanna ni titi aye;
Gbolohun kan lat‘ enu Re
Le w‘arun to buru ju san.

4 mp Bi mo ti s‘aini ranwo to,


Ti mo si pe let‘adagun,
Gbolohun kan yo gbe mi n‘de,
Yo wo mi san lese kan na.

5 Egberun tab‘egba odun,


Bakanna ni nwon loju Re:
Logan, t‘or‘-ofe Re ba de
Arun yo san, emi o bo.

6 f Wa, Onisegun okan mi!


S‘akoko yi n'itewogba:
F‘ipa iwenumo Re han,
F'igbala Re han nisiyi.
Amin.
618 L.M.
Emi fi ohun mi kigbe si Olorun
............ o si fi eti si mi. OD. 77:1.

1 mf Olorun mi, ‗Wo l‘em‘ o pe;


p Ara nni mi, gbo igbe mi:
cr ‗Gba ‗san omi ba bori mi,
ma je k‘okan mi fasehin

2 Iwo Ore alailera,


Tani mba saroye mi fun?
Bikose ‗Wo nikansoso,
T‘O npe otosi w‘odo Re?

3 p Tal‘ o sokun to lasan ri?


‗Wo ko igbe enikan ra?
Se Iwo ni O ti so pe,
Enikan k‘yo wa O lasan?

4 p Eyi ‗ba je ‗binuje mi


Pe, O ko ndahun adura;
Sugbon ‗Wo ti ngbo adura,
Iwo l‘O nse iranwo mi

5 Mo mo pe alaini l‘emi,
Olorun ko ni gbagbe mi;
Eni ti Jesu mbebe fun,
O bo lowo gbogbo ‗yonu
Amin

619 7.7.7,7
Oluwa, mase ba mi wi ni
ibinu Re. OD. 6:1.

1 mf Olorun, fi opa Re
p Ba mi li ori jeje.
Dawo ‘binu Re duro,
Ki nma subu labe re.

2 p Wo ailera mi yi san,
Wo mi, mo nwa ore Re;
Eyi nikan l‘ebe mi,
Wo mi, nipa anu Re.

3 Tal‘ o wa n‘isa-oku,
T‘o le so ti gbala Re?
Oluwa, d‘okan mi ro,
f Fohun, emi o si ye.

4 Wo! o de! o gb‘ebe mi,


O de! ojiji koja;
Ogo si tun yi mi ka,
Okan mi, dide, k‘o yin.
Amin.

620 7.7.7.7.
Emi ki yio fi nyin sile.
Jn. 14:18.

1 Jesu awa nwo O fun


‘Wosan alailera yi
‘Wo lo ti se anu nla,
F‘abirun let‘ adagun.

2 Ko s‘onisegun bi Re;
Ti w‘ara at‘okan san,
‘Wo lo ji omobirin
Jairu dide nin‘oku.

3 Lasaru ti s‘aisan ri,


O ku, a sin i n‘boji,
Sugbpn ‘wo ‘nisegun nla,
J‘oku ‘jo kerin dide.

4 p Jesu jo dari ji wa,


Ba wa wo alaisan yi,
cr K‘o le dide f‘ogo Re,
f Ki a le f‘ope fun O.

5 f Wo ko w‘aisan kan ti ri,


Ninu igbe aye Re,
O ti wi nin‘ anu Re,
Pe ‘leri Re ko ni ye.
Amin.

621 S.M.
Emi o gbekele, emi ki yio si
beru. Isa. 12:2.

1 p M o gbeke mi le O,
Lori ibusun mi,
Gba mi lowo irora mi,
Ki O si wo mi san.

2p Ko s‘elomiran mo,
Ti mo tun gbekele,
Osan fun ‘ya aya Pita
Ninu ailera re.

3 Obinrin igbani,
Pelu isun eje,
Nipa iseti aso Re
O ri ‗mularada.

4p Wo mi san Oluwa,
Ninu ailera mi,
Emi ko gbodo ber‘ aisan,
Gba mo gbekele O.
Amin.

622 S.M.
Alaye, alaye, on ni yio yin O.
Isa. 38:19.

1 cr Ise Oluwa,
Awamaridi ni,
Ohun gbogbo ni mu ‘re wa,
F‘eni to se ‘fe Re.

2 p O ri ailera mi,
Aisan at‘aigbadun
Irora mi losan loru,
Orun ko si l‘oju.

3 p Wo wahala mi yi,
‘Wo Onisegun nla,
So fun mi bi t‘ Hesikaya
―Mo gbo adura re‖.

4 W‘awon to nsike mi,


Ati onisegun,
Wi fun mi bi t‘ Hesikaya,
pp ―Mo ti r‘omije re ‖

5 p Ma wo ailera mi,
Dari ese ji mi,
Wo mi san bit‘ Hesikaya
Si bukun ojo mi
Si bukun ojo mi.

6 f Mu mi wulo fun O,
Lehin ilera mi,
B‘ise mi l‘aye si d‘opin,
Mu mi wo ‘nu ogo.
Amin.

623 7.7.7.7
Tujuka, a dari ese re ji O.
Mat. 9:2.
1 mf Jesu, nigba aye Re,
O ko dekun wo arun;
Igbe irora aisan
Ko kan O k‘o bo ‘le ri,

2 mf Oju anu Re ko gba


K‘elese ma je ‘rora,
Di B‘o tile je pe‘ya na
To si i fun ese re.

3 mp Ninu ija ki emi


Le bo l‘owo iparun,
O ko gbagbe p‘alafia
To s‘eran ara pelu.

4 p B‘alaisan ijo wa wo
Lor‘ akete irora,
Onisegun Ododo,
Se awotan arun re.

5 F‘opo itunu fun u,


K‘o le gbe ara le O,
K‘o mo pe Iwo nikan
L‘O le pa, l‘O le gbala

6 Ma je k‘o siyemejl,
Ki irora mu bo ‘hun
p Fun l‘ebun lati wipe
―B‘iye, b‘iku, ife Re "

7 p K‘o le wu O lati wo
Alaisan ijo wa san,
Bi beko, awa mo pe
Fun rere ni ife Re.
Amin.

624 C .M.
Eniti o si tan gbogbo arun
re. OD. 103:3.

1 mf Eni t‘O la ‘ju afoju,


Ti O mu ope gbon,
At‘ eni t‘O da imole,
Fun eni okunkun.

2 Eni t‘O le fi agbara


F‘awon olokunrun,
Ti O si fi emi iye
p Fun awon t‘o ti ku.
3 Eni fi ‘dasile f‘okan,
T‘O gb‘ eni subu nde,
T‘O si pa ibinuje da
S‘ orin pelu iyin.

4 f WO Onisegun okan mi,


Si O l‘awa nkorin,
Titi aye o fi d‘opin,
Tire l‘ope O se.
Amin.

625 11.12.11. & Ref.


Awon ti n wa Oluwa ki yio se
alaini ohun ti o dara. OD. 34:10.

1 mf Li onakona, ―Oluwa y‘o pese‖


O le s‘ais‘ ona mi, o le sai se tire,
Sugbon l‘ona ara Re li On o pese!
A o gbeke l‘Oluwa On y‘o si pese;
Loto, ao gbeke l‘E On y‘o si pese.

2 L‘akoko t‘o ye, ―Oluwa y‘o pese‖


O le ma se ‘gba mi, o le ma se ‘gba re,
L‘akoko Tire, ―Oluwa y‘o pese.‖

3 Ma beru tori ―Oluwa y‘o pese‖


Eyi ni ‘leri Re, ko s‘oro ti O SO
Ti si yipada: ―Oluwa y‘o pese‖

4 f Yan lo l‘aibikita okun y‘o pinya


A o f‘orin isegun se ona Re l‘ogo
A o jumo gberin, ―Oluwa y‘o pese‖
Amin

626 8.4.8.4.8.8.8.4.
Alafia kio wa bi? Alafia ni.
II A. Qba 4:26.

1 mf N ipa ife Olugbala,


Ki y‘o si nkan;
Oju rere Re ki pada ,
Ki y‘o si nkan;
p Owon l‘eje t‘o wo wa san;
Pipe l‘edidi or‘ofe;
p Agbara l‘owo t‘o gba ni
Ko le si nkan.

2 p Bi a wa ninu iponju,
f Ki y‘o si nkan;
Igbala kikun ni tiwa,
Ki y‘o si nkan,
cr Igbekele Olorun dun;
Gbigbe inu Kristi l‘ere,
Emi si nso wa di mimo,
Ko le si nkan.

3 f Ojo ola yio dara,


Ki y‘o si nkan,
cr ‘Gbagbo le korin n‘nu ‘ponju
Ki y‘o si nkan,
mf Agbekele ‘fe Baba wa;
Jesu nfun wa l‘ohun gbogbo
di Ni yiye tabi ni kiku;
f Ko le si nkan.
Amin.

627 8.8.8.D.
Nitoriti afi ipile re sole lori
apata. Mat. 7:25.

1 f Igbagbo mi duro l‘ori,


Eje at‘ododo Jesu,
di Nko je gbekele ohun kan,
cr Leyin oruko nla Jesu.
ff Mo duro le Kristi Apata,
Ile miran, iyanrin ni.

2 f B‘ire-ije mi tile gun,


Or‘-ofe Re ko yi pada;
B‘o ti wu ki iji na le to
Idakoro mi ko niye.

3 f Majemu, ati eje Re


L‘em‘o ro mo, bi ‘kun mi de;
di ‘Gbati ko s‘atileyin mo
f On je ireti nla fun mi.

4 f ‘Gbat‘ipe ‘keyin ba si dun,


mp A! mba le wa ninu Jesu;
cr Ki nwo ododo Re nikan
Ki nduro niwaju ite.
Amin.

628 C.M.
Bu si igbagbo wa. Lk. 17:5.

1 mf Aba le n‘ igbagbo aaye,


B‘o ti wu k‘ota po,
Igbagbo ti ko je mi ra
Fun aini at‘ osi.
2 p Igbagbo ti ko je rahun
L‘abe ibawi Re,
cr Sugbon ti nsimi l‘Olorun
Nigba ibanuje.

3 mf Igbagbo ti ntan siwaju


‘Gbat‘ iji ‘ponju de;
Ti ko si je siyemeji
N‘nu wahala gbogbo.

4 mf Igbagbo ti ngb‘ona toro,


p Titi emi o pin,
cr Ti y‘o si f‘imole orun
Tan akete iku.

5 mf Jesu f‘igbagbo yi fun mi,


Nje b‘o ti wu k‘ori,
cr Lat‘ aye yi lo, un o l‘ayo
Ilu orun rere.
Amin

629 6.7.7.7.6. & Ref


Nipa ore-ofe ni a ngba nyin la. Efe. 2:8.

1 mp Ekun ko le gba mi,


Bi mo le f‘ekun we ‘ju;
Kole mu eru mi tan,
Ko le we ese mi nu;
Ekun ko le gba mi,
mf Jesu sun, O ku fun mi.
O jiya l‘ori igi,
Lati so mi d‘omnira,
f On na l‘O le gba mi.

2 mf Ise ko le gba mi,


Ise mi t‘odaraju,
Ero mi t‘o mo julo,
Ko le so ‘kan mi d‘otun
Ise ko le gba mi.

3 mf ‘Duro ko le gbami,
Eni t‘o junu ni mi,
L‘eti mi l‘anu nke pe,
Bi mo ba duro, un o ku;
Duro ko le gba mi.

4 f Igbagbo le gba mi,


Je ki ngbeke l‘Omo Re
Je ki ngbekele ‘se Re
Je ki nsa si apa Re,
Igbagbo le gba mi.
Amin.

630 8.8.8.D.
Alabukun li awon ti ko ri Mi,
sugbon ti nwon gbagbo. Jn. 20:29.

1 mp Om‘Olorun, a ko ri O,
‘Gba t‘O wa s‘aye, iku yi;
Awa ko ri ibugbe Re;
Ni Nasareti ti a gan,
Sugbon a gbagbo p‘ese Re
Ti te ita Re kakiri.

2 p A ko ri O lori igi
T‘eyan buburu kan O mo
A ko gbo igbe Re, wipe
―Dariji won, tor‘ aimo won‖
f Sibe, a gbagbo pe: 'ku Re
Mi aye, o si m'orun su.

3 mf A ko duro l'eti 'boji


Nibiti a gbe te O si;
A ko joko ‘nu yara ni,
A ko ri O l‘oju ona
F Sugbon a gbagbo p‘angeli
Wipe, ―lwo ti ji dide‖.

4 mf Akor‘awon wonni t‘O yan


Lati ri ‘goke - r‘orun Re;
cr Won ko fi iyanu woke
p Won si feru dojubole
Sugbon a gbagbo pe won ri O
Bi O ti n goke lo s‘orun.

5 mf Iwo njoba l‘oke loni,


‘Wo si nbukun awon Tire
di Imole ogo Re ko tan
Si aginju aye wa yi,
f Sugbon, a gba oro Re gbo Jesu,
Olurapada wa.
Amin.

631 C.M.
Laisi, igbagbo, o soro lati wu u.
Heb. 11:6.

1 mf Igbagbo l‘ategun t‘o so


Orun at‘aye po;
On l‘Olugbala fi sise
Iyanu Re l‘aye.

2 mf Igbagbo ni keke Enok‘


Ti o gun lo s‘orun;
On l‘o gba Ju meta ni la,
L‘o gba Daniel‘ pelu.

3 mf Lor‘ igbagbo ni Noa ko


Oko igbala ni;
On l‘agbara t‘o gb‘ Elija
Wo inu sanma lo.

4 mf Igbagbo n‘ipile ‘reti,


O le se ohun nla;
Otito igbagbo le mu
Ohun ti ko si wa.

5 mf On l‘agbara ase ‘kini


T‘o mu ki aye wa;
On l‘agbara ikeyin ti
Yo gba elese la

6 f ―K‘ori fun o b‘igbagbo re‖


L‘Olugbala wawi;
A! je ki ngba ohun nla gbo
Si O, Oluwa mi.
Amin

632 C.M.
Ma da mi ro. Gen. 24:56.

1 mf L ‘ona gbogbo t‘Oluwa yan,


Ajo mi lem‘o to
Ma da mi ro, eyin mimo
Emi o ba yin lo

2 Bi Jesu nlo ninu ina,


Emi o to leyin
F Ma da mi ro l‘emi o ke
B‘aye d‘oju ko mi.

4 Ninu isin at‘idanwo


Em‘o lo l‘ase Re,
Ma da mi ro, emi o lo,
S‘ile Imanuel‘.

4 ‘Gba Olugbala mi ba pe
Sibe k‘igbe mi je
Ma da mi ro iku ma bo
Un o ba O LO l‘ayo.
Amin.

633 11.11.11.11. & Ref.


E ma si se fi aye fun esu.
Efe. 4:27

1 mp Ma f‘ara fun ‘danwo, nitor‘ese ni,


Isegun kan yo tun fun O l‘agbara;
Ja bi okunrin, si bori ‘fekufe,
mf Sa tejumo Jesu, y‘O mu o laja.
pp Bere ‘ranwo at‘agbara lodo Olugbala,
mf O se tan fun iranwo, Oun y‘O mu o la ja

2 mp Ma kegbe buburu, ma Soro ibi,


Mase pe oruko Olorun l‘asan;
Je eni ti nronu at‘olotito;
mf Sa tejumo Jesu, y‘O mu O la ja.

3 mf Olorun y‘O f‘ade f‘eni t‘o segun,


Ao fi ‘gbagbo segun, b‘ota nde si wa;
Kristi y‘O so agbara wa di otun,
Sa tejumo Jesu, y‘O mu o la ja.

634 C.M
Ki o ri fun nyin, gege bi igbagbo nyin.
Mat. 9:29.

1 Igbagbo t‘ori ‘leri na


Ti ko ka soro si,
T‘o nwo Olorun nikan,
T‘o nwipe, ―Ao segun‖

2 A! Eyi koja oye mi


Sugbon nki yo beru
Tor‘ Oluwa ti se ‘leri,
Oro Re ki tase

3 Igbagbo nla ti ki tase


Baba jo fi fun mi,
Igbagbo to duro gangan
Titi y‘o fi segun.
Amin.

635 7.7.7.5.
Bere a o si fifun nyin. Mat. 7:7.

1 mf Y‘o dahun gbogb‘ adura


Ileri ati ‘fe Re
Ko sa ti yi pada ri;
Ogo f‘oko Re

2 mf Y‘ o dahun gbogb‘ adura


Un o ro mo ileri Re
Mo mo On ko je da mi
Ogo f‘oko Re.

3 mf Y‘o dahun gbogb‘adura


Je ka bere ni ‘gbagbo
Emi Re nran ni lowo
Ogo foko Re

4 mf Y‘o dahun gbogb‘ adura


Wa sibi ite anu
O ri idaniloju
Ogo foko Re
Amin.

636 8.7.8.7.8.7.
Oluwa li Oluso-agutan mi.
OD. 23:1.

1 f Jesu l‘Olusagutan mi,


Nje k‘iberu lo jina:
LOWO kiniun at‘ ekun,
LOWO eranko ibi,
Yio so agutan Tire,
Jesu y‘o pa Tire mo.

2 Nigb‘ ota fe lati mu mi,


On ni: Agutan mi ni,
p O si ku, lati gba wa la;
Jesu ife kil‘ eyi?
Isegun ni ona Tire,
Ko s‘ohun t‘o le se e.

3 Lona iye l‘o ndari mi,


Let‘ isan t‘o nsan pele;
Ninu oko tutu yoyo,
Nib‘ ewe oro ki hu,
Nibe ni mo gbohun Jesu,
Nibe l‘o m‘okan mi yo.

4p Oba mo ba nlo s‘isa oku,


B‘eru tile wa l‘ona,
Emi ki o berukeru,
Tor‘ Olusagutan wa;
f ‘Gba mo r‘ogo at‘opa Re
Mo mo p‘agutan Re yo.
Amin.
637 C.M
Abrahamu si pe oruko ibe na ni
Jehofa-jire. Gen. 22:14.

1 mf Ko to k‘awon mimo beru,


Ki won SO ‘reti nu:
‘Gba won ko reti ranwo Re,
Olugbala y‘o de.

2 Nigbati Abraham mu obe,


Olorun ni, ―Duro‖;
Agbo ti o wa lohun ni,
Y‘o dipo omo na.

3 p ‘Gba Jona ri sinu omi,


Ko ro lati yo mo;
Sugbpn Olorun ran eja,
T‘o gbe lo s‘ebute.

4 B‘iru ipa at‘ife yi


Ti po l‘oro Re to!
Emi ba ma k‘aniyan mi,
Le Oluwa lowo!

5 f E duro de iranwo Re,


B‘o tile pe, Duro,
B‘ileri na tile fale,
Sugbpn ko le pe de.
Amin.

638 8.8.8.D.
Nitori ti itara ile re ti je mi tan.
OD. 69:9.

1 mf Fun mi n‘igbagbp to le so
Oke giga di petele;
Fun mi ni ife adura,
Ti nfe lati tun ‘le Re ko;
cr K‘ife Re bori okan mi,
Ko si gba gbogb‘ emi mi kan

2 mf Mo nfe ife to lagbara,


Mo nfe itara to gbona,
cr Ki nyo elese n‘nu ina,
Ki nja won lowo iparun,
Ki ndari won sod‘Olorun
Ki nf‘eje Jesu pa ‘na won.

3 mf Mo fe ra ‘gba to lo pada,
cr Ki npe laye nitorina,
Ki nlo ara mi fun awon
Ti ko ti mo Olugbala;
Ki nfipe mi han lara won,
Ki nsi ma mi kik‘ife Re.

4 mf Gba ebun ati ise mi


S‘owo rere Re, Oluwa;
Jeki nma wasu Oro Re,
cr Ki nwa laye fun ogo Re,
Ki nlo gbogbo akoko mi
N‘ikede Ore elese

5 mf Bus‘ okan mi, mu ko gbona,


K‘O si f‘ife mimo kun un!
cr Beni un o lo gbogbo ‘pa mi,
Un o f‘itara Tire fe won;
Un o si to won si iha Re,
Awon agutan t‘O ku fun.
Amin.

639 C.M.
E ma sanu awon elomiran,
E ma gba awon Elomiran la.
Juda 1:22-23.

1 mf A ni ‘se to logo kan se,


Ise ribiribi;
Ki gbogbo aye dapo mo wa,
Lati se ise na.

2 mp ‘Banuje kun opo ile,


T‘alafia ko si;
cr Je k‘a f‘ayo kun ‘le wonyi,
K‘a f‘Olugbala han.

3 p Eru o ti po yi wa ka,
Won nyira n‘nu egbe;
cr Je k‘a da ewon t‘o de won
K'a pa ibi na re.

4 p Opo aya pelu iya,


Nsokun fun ‘banuje;
cr Je ki a tu won ni inu
Pe, ireti si mbe.

5 p Opolopo l‘awon omo


Ti mbe ninu ese;
cr Je k‘a yo won ninu okun
Si inu imole.
6 f Je k‘a wo ihamora wa
Olorun n‘ipa wa,
On l‘o nsamona ogun wa,
Si ‘segun t‘o daju.
Amin.

640 7.7.7.7
Ki ife ara ki o wa titi. Heb. 13:1.

1 mf Jesu, Iwo ni a nwo,


K‘a repo l‘oruko Re;
Alade alafia
Mu k‘ija tan l‘arin wa

2 Nipa ilaja Tire


p Mu idugbolu kuro;
Da wa PO ni isokan;
F‘itegun Re sarin wa.

3f Je k‘a wa ni okan kan


K‘a se anu at‘ ore;
K‘a tutu l‘ero, l‘okan
Gege bi Oluwa wa,

4 f K‘a s‘aniyan ara wa;


K‘a ma r‘eru ara wa;
K‘a f‘apere fun Ijo,
B‘onigbagbo ti gbe po

5f K‘a kuro ni ibinu,


K‘a simi le Olorun;
K‘a so ti ‘bu ife
At‘ ogo iwa mimo.

6 ff K‘a fayo kuro l‘aye,


LO si ijo ti orun,
K‘a f‘iye angeli fo,
K‘ale ku b‘eni mimo
Amin
641 C.M.
E ma ru eru omonikeji nyin, ki e si fi
be mu ofin Kristi se.
Gal. 6:2.

1 f Alabukun ni fun ife


Ti ki o je k‘a ya;
Bi ara wa jina s‘ara,
Okan wa wa l‘okan.
2 mf Da opo emi s‘ori wa,
Ona t‘o la l‘a nto;
Nipa ti Jesu l‘a si nrin,
Iyin Re l‘a nfi han.

3 Awa ba ma rin l‘ona RE,


K‘a ma si m‘ohun kan;
K‘a ma fe ‘hun kan bikose
Jesu t‘a pa fun wa.

4 f K‘a sun mo O girigiri


Ati si ona Re;
K‘a ma r‘ore gba lodo Re,
ff Ekun ore-ofe.
Amin.

642 C.M.
Kiyesii, o ti dara, o si ti dun to fun awon
ara lati ma jumo gbe ni irepo.
OD. 133:1.

1 f Wo b‘o tidun, t‘o si dara


Lati gbe ni ‗repo;
Be l‘o ye fun awon ara
Lati jumo gbe po

2 O dabi ororo didun


Ni irungbon Aaron;
Kikan re m‘aso re run ‗re
O san s‘agbada re

3 p O dara b‘iri owuro


T‘o nse s‘oke Sion;
Nibi t‘Olorun f‘ogo han,
Iye ainipekun
Amin.

643 CM
Sugbon eyiti o tobi ju ninu won ni ife
I. Kor. 13:13

1 Alafia ni f‘okan na
Nibit‘ ife gbe wa;
Ife ni o tobi julo
Ninu gbogbo ebun.

2 mf Asan ni gbogbo imo je,


cr Asan ni ‘beru wa:
Ese y‘o bori okan wa
B‘ife ko si nibe

3 Ife l‘ondari ese wa


Si ona igboran;
Esu mo yi o nwa riri;
‘Tori ko le n‘ife.

4 Ife nikan ni y‘o r‘opin


Igbagbo on ‘reti;
Nipa re l‘a o ma korin
Loke orun lohun.

5 K‘a to pa ago ara ti


Ile okunkun yi;
lye ife y‘o gbe wa fo
LO ri Olorun wa.
Amin.

644 S.M.
Ijo awon ti o gbagbo si wa
li okan kan ati inu kan.
Ise A. 4:32.

1 mf Awa wa yin ife Re


To so okan wa po,
T‘a njumo n‘idapo didun
Bi won ti nse loke

2 Nib‘ ite Baba wa,


F A nf‘itara bebe;
A njumo so edun wa fun,
A si nr‘itunu gba

3 mp A mb‘ara wa kedun
A mb‘ara wa y‘ayo;
Ohunkohun t‘o wu ko de,
A njumo f‘ife pin

4 mp B‘ipinya base de,


O mba wa ninu je;
Mf Ibi kan wa fun idapo
Ti ore nri ‗ra won

5 mf Eyi n‘ireti wa,


Ti nso okan wa ji;
f Pe ao pade lai pinya
l‘ese Jesu l‘oke

6 f A o bo low‘aniyan,
Ao o lowo ese,
Ife pipe y‘o so wa po
Titi ayeraye
Amin.

645 C.M
Gbogbo nwon fi okan kan wa nibi
Kan. Ise A. 2:1

1 mf Eje k‘a yin Olugbala


T‘O da wa po l‘okan
T‘O pase k‘a tun jo pade,
Lati wa oju Re.

2 O pase k‘a gbe ‗ra wa ro:


Awa jumo nlepa
Ipe giga wa t‘o logo
N‘nu isokan emi

3 cr Ebun t‘O fun wa, lokokan


L‘awa nfi ayo lo;
Or‘ofe na nsan larin wa,
Ninu ife mimo

4 cr Ero at‘oro wa j‘okan


Ife wa si j‘okan
Awa wa n‘irepo pipe
Li oruko Jesu

5 A nse ajopin ayo wa,


At‘alafia wa,
Alafia t‘aye ko mo,
Ayo t‘a ko le so.

6 B‘idapo wa ninu Jesu


Ba dun bayi laye,
F Aup wa y‘o ti tobi to
‗Gba ba yi ‗te Re ka!
Amin.

646 8.8.8.8.D.
O ti dara, o si ti dun-to fun awon
ara lati majumo gbe ni irepo.
OD. 133:1.

1 f O ti dara to lati ri
Awon ara ni irepo,
T‘ero at‘oro won j‘okan,
Ti won nfi ‘gbagbo at‘ife
Jumo nwa ohun ti orun,
Won nkede okiki Jesu.
2 mf Olorun, Olore-ofe,
T‘mu Re dun s‘isokan wa,
On f ayo busi ‘pade wa;
O nf‘itura mu wa soji
O ntu‘bukun Re sori wa,
O nfun wa n‘ibale okan.

3 mf Jesu, Okuta igun‘le


Je k‘ awon t‘Emi Re dapo
Ma wa n‘nu isokan pipe;
Je k‘ a ma gbe ‘nu Emi Re
K‘a f‘apere ‘sokan mimo
Lele fun ijo Re nihin.

4 f Je k‘a ma fi mo ara wa
F‘ebun or‘-ofe Re fun wa
Lati ma ya wa si mimo;
Titi ao fi d‘eni pipe,
T‘ a o ba awon t‘oke pade
T‘ ao si ni ipo lodo Re
Amin.

647 6.6.6.6.8.8.
Kiyesii, o ti dara, o si ti dun to fun
awon ara lati ma jumo gbe ni
irepo. OD. 133:1.

1 mf W o b‘o ti dara to
Lati wa l‘alafia;
Eso ododo yi
f Ti ndun m‘Oba wa to,
Nigbat‘ara wa n‘irepo,
Ayo isokan ti dun to.

2 Nibiti sokan kan,


Nibe l‘ore-ofe
Ntan si ohun gbogbo,
O si nya si mimo;
O nwa s‘okan ti nreti re,
O si nfun-ni lohun t‘orun.

3 mf Lojojumo l‘a nri


Or‘ofe titun gba;
f Iri ‗bukun ti nse
sor‘ oke Hermoni!
O nse sori Sion pelu;
A npin n‘nu ebun ara wa.

4 cr Nisiyi, Oluwa
Nro ojo ibukun
Pelu itura Re,
Ti ninu okan soji;
Akoro at‘arokuro,
Ife Olorun at‘eniyan.

5 Ipejopo ara
Ti nwa alafia,
Li On se ileri
Lati fi ire fun;
mf Y‘o fi opo ‘re-ofe Re.
F‘awon t‘o pejo l‘oko Re.

6 f O nf‘ ekun ore Re


Fun awon t‘o pejo
Awon ara Sion,
Omo-‘bile orun
O nfi isura Re fun won,
Ati iye ainipekun.
Amin.

648 7.7.7.7
E wa, e je ki a korin si Oluwa.
OD. 95:1.

1 mf E wa, e jek‘a jumo


F‘orin mimo yin Kristi;
K‘a f ohun kan fi ogo
Fun Oluwa gbogbo wa.

2 f K‘agb‘okan at‘ohun wa
Soke bi t‘aye ‘gbani;
K‘a bere ayo orun;
K‘a s‘ajo ase-ife.

3 A ngbiyanju n‘nu ife;


cr Jek‘ ina ife soji,
Ti njo n‘nu awon martyr
T‘oku n‘tori Olorun.

4 Awa le ni‘fe bi won,


Ale pin n‘nu ayo won,
A gba wa lowo.‘ binu,
Nipa igbagbo kanna.

5 f A nkorin iyin Jesu,


Okanna l‘ana, l‘oni;
Okanna nigbagbogbo,
Olore-ofe julo.
6 A duro f‘Oluwa wa,
Bi ‘mole ni‘le okun;
Ajewo Jesu t‘o ku
Awa ni eleri Re.

7 f Eleri pe, Krist‘ ti ku,


A kan awa Re mo ‘gi,
Krist‘ ti da ide iku,
Emi iye Re l‘a nmi;

8 f Krist‘ti goke lo s‘orun,


On ni ife wa nfa si;
O wa l‘otun Olorun;
Nibe l‘ao ba joba.
Amin

649 8.7.8.7. & Ref.


Oluwa, Iwo ni ipin mi. OD. 119:5 7.

1 mf Kristi ni ipin mi titi,


On l‘o ngba mi nin‘ese.
O je ona igbala mi,
F Eri yi wa l‘okan mi,
Eri yi wa l‘okan mi,
(L‘okan mi)
Jesu gba mi low‘ese
(Low‘ ese)
ff Mo l‘ayo laya Re,
Or‘-ofe Re gba mi,
Eri yi si wa lokan mi
(L'okan mi)

2 mf On ni odi agbara mi,


Amona at‘Oba mi
On si ni Olupamo mi,
Nje mo ‘le fayo korin.

3 f Iyin fun Eni t‘O ra mi,


Iyin f‘Eni ti a pa,
Nje emi bo, Aleluya!
Iyin fun oro‘yanu.
Amin.

650 14.10.8.8.15.10.
Nitori ojo wa gbogbo nyi po lo
ninu Ibinu Re. awa nlo ojo wa bi
ala ti a nro. OD. 90:9.

1 p Akoko wa gbogbo l‘o nyara sure koja lo


Won kun fun igba aro on ‘rora,
mf Sugbon 'fe Olorun npo si,
B‘ojo atipo wati ngun
Bi nko tile fo ohun, okan mi nso inira
na;
Un o sunmo Olorun, un o sunmo O.

2 mp Iseju kokan nsun mi mo igbati un o


pinya
Pelu aye t‘o se owon fun mi
Iri ile si nhan si mi,
‘Ranti orun s‘owon fun mi
Ju ti aye pelu gbogbo ogo ati oro re,
Un o sunmo Olorun, un o sunm O.

3 mf Eni ‘rapada Oluwa, e korin igbagbo


E fi ara ti oro Olorun,
E duro n‘nu ileri Re,
Bi abo, e sa s‘abe Re
f Fi igboya rin ona t‘awon ajeriku ti rin
Un o sun mo Olorun, un o sun mo O.
Amin.

651 7.4.7.4.6.6.6.4. & Ref.


Lati isisiyi lo afi ade ododo lele
fun mi. II Tim. 4:8.

1 f Emi y‘od‘ade wura


‘Gba mba dele;
Un o bo lowo aniyan
‘Gba mba dele;
Un o wo aso ogo
Em‘ o korin itan,
Ti Jesu t‘o ra mi
‘Gba mba dele
ff ‘Gba mba dele
‘Gba mba dele) 2x
Ibanuje y‘o dopin)
‘Gba mba dele)

2 f Okunkun ko ni si mpo
‘Gba mba dele;
Un o bo si imole nla
‘Gba mba dele;
Imole lat‘oke,
Si ipa ona mi,
Ti y‘o ma to mi lo
Titi dele.

3 f Un o r‘oju Oluwa mi,


‘Gba mba dele;
Un o korin ore-ofe
‘Gba mba dele;
Un o duro n‘waju Re,
Un o si ma juba Re,
Titi lae lodo Re
‘Gba mba dele.
Amin.

652 C.M.
Lati isisiyi lo a fi ade ododo lele
fun mi. II Tim. 4:8.

1 mf Iro ayo t‘ihin-rere;


Krist‘ y‘o han ninu mi!
Ani emi y‘o r‘oju Re,
Un o di mimo nihin.

2 Okan yi y‘o je ile Re;


cr Mo gbohun Emi Re
Wipe, loto, mo mbo kankan
On ki se eleke.

3 mf Ade ogo ti ododo


Ti mo nwo niwaju,
‘Gba m‘ba segun lagbara Re
Un o gbamu, un o si de.

4f Mo f‘ayo wo ile ‘leri


Lati oke Pisga,
Ireti mi ki o saki
Ireti t‘o logo!

5 cr O mbe ago amo yi wo,


O ngbon ‘le ti y‘o gbe;
mf Krist‘ ba je wa l‘oj‘ayo yi,
Si nu tempili Re!

6 Mo mo pe O wa pelu mi,
cr Sugbpn eyi ko to,
A fi b‘O fi paradise
Mule li okan mi.

7 mp Olorun mi, f‘ara Re han,


Kun gbogbo afo yi;
IWO l‘o le kun okan mi,
Ma bo, Olorun mi!
Amin.

653 6.4.6.7.7. & Ref.


E fi okan nyin bale; nitori ipadawa
Oluwa ku si dede. Jak. 5:8.

1 mf J esu le de loni
Ojo ayo!
f Un o si ri Ore mi,
Gbogbo wahala y‘o tan
Bi Jesu ba de loni.
f Ojo ayo!
Ojo nla Ologo.
mp Un o fi suru duro d‘ojo na
Laipe un o ri Oluwa mi
f Ojo ayo!
Ojo nla Ologo.

2 mf Boya un o lo loni
Ojo ayo!
f Dabi eni ngb‘ohun
Orin awon ayanfe
Bi pe loni ni uno lo

3 mf Emi o se kanju
Ojo ayo?
f Eru ‘ji ko ba mi
‘Mole tan l‘ebute na
Nitori O wa n‘tosi.

4 mf Un o maje oloto,
Ojo ayo!
F Un o si makede Re,
Bi mo ti feran Re to,
On l‘ohun gbogbo fun mi.
f Ojo ayo!
Ojo nla Ologo
mp Un o fi suru durod‘ojo na
Laipe un o ri Oluwa mi
F Ojo ayo!
Ojo nla Ologo.
Amin.

654 8.8.8.8.8.8.
Won nyo niwaju re gege bi ayo
ikore. Isa. 9:3.

1 mf Oluwa ‘kore, ‘Wo l‘a yin;


Ileri Re ‘gbani ko ye
Orisi igba si nyipo,
Ododun kun fun ore Re;
L‘ojo oni, awa dupe,
Je k‘iyin gba okan wa kan
2 mf B‘akoko‘rugbin mu wa yo;
B‘igba erun nmu oru wa;
‘Gbat‘ owo ojo ba nrinle;
Tab‘ igbati ‘kore ba pon,
F ‘WO Oba wa l‘a o ma yin;
‘WO l‘alakoso gbogbo won.

3 f Ju gbogbo re lo, nigbati


Owo re fun opo kale
‘Gbati ohun ayo gb‘ile
B‘eda ti nko ire won jo;
ff Awa pelu y‘o ma yin O
Oore Re ni gbogbo wa npin.

4 mf Oluwa ‘kore, Tire ni


Ojo ti nro, orun ti nran;
Irugbin ti a ngbin sile,
Tire l‘ogbon ti nmu dagba;
Otun l'ebun Re l‘ododun;
Otun n‘iyin Re l‘enu wa.
Amin.

655 7.7.7.7.D.
Eniti nji ekun rin lo, ti o si gbe
Irugbin lowo, loto yio fi ayo pada wa,
yio si ru iti re. OD. 126:6.

1 f Wa, eyin Olope wa,


Gbe orin ikore ga,
Ire gbogbo ti wole
K‘otutu oye to de;
mf Olorun Eleda wa,
ff L‘o ti pese f‘aini wa;
Wa k‘arele Olorun
Gbe orin ikore ga.

2 mf Oko Olorun l‘a je


Lati s‘eso iyin Re
Alikama at'epo,
Ndagba f‘aro tab‘ayo
cr Ehu su, ipetele
Siri oka si kehin;
p Oluwa ‘kore mu wa
Je eso rere fun O.

3 mf N'tori Olorun wa mbo


Y‘o si kore Re sile;
On o gbon gbogbo panti
Kuro l‘oko Re njona;
Y‘o f ase f‘awon angel‘
Lati gba epo s‘ina;
Lati ko Alikama
Si aba Re titi lae.

4 Beni, ma wa, Oluwa


Si ikore, ikeyin
Ko awon eeyan Re jo
Kuro l‘ese at‘aro;
So won di mimo laelae
Ki won le maa ba O gbe
Wa t‘Iwo t‘angeli Re
Gbe orin ikore ga.
Amin.

656 8.7.8.7.& Ref.


Ojo ibukun yio si ro.
Esek. 34:26.

1 mf Ojo ibukun y‘o si ro;‖


Ileri ife l‘eyi
A o ni itura didun
Lat‘odo Olugbala
ff Ojo ibukun,
Ojo ibukun l‘a nfe,
Iri anu nse yi waka
Sugbon ojo l‘a ntoro.

2 f ―Ojo ibukun y‘o si ro,‖


Isoji iyebiye;
L‘ori oke on petele
Iro opo ojo mbo

3 f ―Ojo ibukun y‘o si ro,‘


Ran won si wa, Oluwa;
Fun wa ni itura didun
Wa Tola fun orp Re*

4 f ―Ojo ibukun y‘o si ro,‖


Iba je le ro loni!
B‘a ti njewo f‘Olorun wa
T‘a npe oruko Jesu.
ff Ojo ibukun,
Ojo ibukun l‘a nfe,
Iri anu nse yi wa ka
Sugbpn ojo l‘a ntoro.
Amin.

657 7.6.7.6.D. & Ref.


Niwon igba ti aye yio wa, igba irugbin
ati ikore ki yio dopin. Gen. 8:22.
1 Aroko, a funrugbin
Sinu oko gbogbo,
cr Sugbpn owo Olorun
L‘o mu ‘rugbin dagba;
O ran otu at‘oru
Lati mu eso pon,
Efufu ati orun,
At‘ojo t‘o nrinle
mf Ebun rere gbogbo
Lati orun wa ni;
Sope f‘Oluwa, e sope
Fun gbogbo ife Re.

2 f On nikan li
Eleda Orun ati aye;
O fun itanna l‘ewa,
O mu irawo tan;
Iji gba ohun Re gbo,
O mbo awon eye;
Paapaa awa omo Re
L‘O mbo lojojumo.

3 f Baba, a sope fun O,


F‘ohun rere gbogbo,
Fun ‘gba ‘rugbin on ‘kore
F‘emi ‘lera, onje;
Gba ebun ti a mu wa
Fun iseun-ife Re.
Si gba okan ope wa,
‘Wo sa fe eyi ju.
Amin.

658 7.6.7.6.Triple
Afunrugbin kan jade lo lati
funrugbin. Mat. 13:3.

1 cr A gbe lo fun ‘rugbin re;


‘Rugbin si farasin
Ojo pupo l‘o koja
Ki o to ru jade;
mf Oorun ti nran mu gbona,
Ojo si mu dagba,
Oko pon fun ikore
Loju wa leekan si,
f Yin Afunrugbin torun
T‘o fi eso fun wa,
T‘o bomirin lakoko
T‘o si mu pon fun wa.
2 f Wo! Afunrugbin t‘orun
Nlo funrugbin iye
O nf‘owo at‘ ese Re
Fon oro igbala,
Laarin Ijo Re nihin,
Okan wa l'oko Re;
mp E jek‘ a s‘eso pupo
Fun ere laalaa Re
‘Kore na y‘oti dun to
T‘o kun f‘opo ire,
Eyi l‘ope otito,
Akoso aye wa.

3 mf Jesu nfunrugbin miran


Sinu ile mimo,
‘Gbati ile gba oku
Awon ti On ku fun;
f B‘ako tile leri won
A mo pe won y‘o ji;
O daju pe won wa ni
ff Paradise ayo,
Ile ikore t‘o kun
F‘awon eni-mimo
Ti won wo ewu Kristi,
Ti won d‘ade wura!

4 cr Afunrugbin ti orun
Y‘o kore n‘ijo kan,
f Y‘o si f‘ayo pada wa
Pelu awon Tire;
‘Gbana y‘ose idajo
Y‘o si fe iyangbo
Sinu ileru ina
Ti ki o ku titi;
mp Iwo Olukore nla,
Saanu wa l‘ojo na
T‘Iwo y‘o se ikore,
Ma si se ta wa mi
Amin.

659 8.7.8.7.D.
Emi ko pa iseun ife Re ati otito Re
Kuro lodo ijo nla ni. OD. 40:10.

1 f Oluwa, a gbe okan wa


Si O n‘nu orin iyin;
A m‘ore ope wa fun O
Pelu iho ayo nla;
Gbogbo papa f‘ewa bora
Awon oke nho f‘ayo
Oka po l‘afonifoji
Tobe ti won fi nkorin.

2 mf Loni, ojo ikore wa,


Awa jewo ore Re,
f Awa f‘ope mu ebun wa,
Akoso ibukun Re
‘Wo l‘o nfi ore-ofe bo
Okan awa eda Re,
‘Wo ti npese onje ojo,
Fi onje orun bo wa.

3 cr A nfarada oru ojo,


Laalaa a si ma su-ni;
mf Sugbon nigbati oorun wo
'Simi de fun alaare;
mp Se wa l‘eni itewogba,
‘Gbat‘ angeli ba nkore,
K‘a je alikama Kristi
Ti O n y‘o to si aba.

4 mf Abukun n‘ile Olorun


‘ Bit‘ awon mimo wa lae
Papa wura teju nibe
Odo re ndan bi Kristal,
ff Orin egbe mimo t‘ohun
Dapo mo tiwa loni;
‘Bukun orin ‘kore na po
Ti a o maa ko titi.
Amin.

660 6.5.6.5.Triple
Ojo oni ni yio si ma se ojo iranti fun yin,
enyin o si ma fe li ajo fun Oluwa.
Eks. 12:14.

1 f Adupe Oluwa
F‘ajodun oni,
O da emi wa si,
Ogo f‘oko Re;
ff Pelu orin ayo
L‘a o fi josin
Fun‘bukun aye wa
On ‘reti orun.
ff Ajodun de, e yo!
Ke, Aleluya!
A m‘ore ope wa,
Tewo gb‘ore wa.

2 mp Opo l‘elegbe wa
Ni ko tun si mo;
Opo ti sako lo
Kuro lodo Krist‘
f A dupe Oluwa
Pe O da wa si,
O si tun ka wa ye
F‘ajodun oni.

3 mf Baba wa li orun,
Awa se ‘pinu
Pe a o sin Jesu
L‘ojo aye wa,
A o sise fun ‘dagba
Soke ijo wa
Tit‘ ao fi je ‘pe Re
Fun ‘simi orun.

4 mf ‘Wo Oluw‘ ajodun


A fope fun O,
di Je k‘ire ajodun
Kari gbogbo wa;
A be O, Olorun,
Fun wa l‘agbara
Lati sin O d‘opin
Ojo aye wa.
Amin.

661 6.6.6.6.D.
Awon enia mimo Re yio si mafi
ibukun fun O. OD. 145:10.

1 f Ogo, iyin, ola,


Fun Olugbala wa
T‘o da emi wa si
Titi d‘ojo oni
Ayo kun okan wa
Fun anfani nla yi
Lati sise fun O
N‘nu ogba Re laye.

2 f A dupe fun ‘toni


On agbara t‘emi
At‘ebun ife nla
Ti o fi so wa po,
Olusagutan wa,
Tewo gba iyin wa;
Nitori anu Re
Se wa l‘okan laelae.

3 mp Bukun wa, Oluwa,


Loni ajodun wa,
Ran ami Re si wa
K‘a layo n‘nu ‘sin Re
Ka si s‘aseyori
N‘nu ise isin wa
K‘a si fi Jesu se
Igbekele wa lae.

4 mf Eleda, Oluwa,
Orisun ‘gbala wa,
di Se waye f‘ajodun
Ti ibugbe loke;
N‘ipari ajo wa
N‘nu aye osi yi,
K‘a le ni ibugbe
Lodo Re Oluwa.
Amin.

662 8.8.8.4.
Nitori ohun gbogbo odo Re ni o ti wa,
ati ninu ohun owo Re li awa tifi fun o.
I Kro. 29:14.

1 f Oluwa orun oun aye,


‗Wo n‘iyin at‘ope ye fun fun:
Bawo la ba ti fe O to!
Onibu ore.

2 Orun ti nran, at‘afefe,


Gbogbo eweko nso ‘ fe Re;
‘Wo l‘O nmu irugbin dara,
Onibu ore.

3 Fun ara lile wa gbogbo,


Fun gbogbo ibukun aye
Awa yin O a si dupe;
Onibu ore.

4 p O ko du wa li Omo Re,
O fi fun aye ese yi,
Pelu Re l‘ofe l‘o nfun wa
L‘ohun gbogbo.

5 mf O fun wa l‘Emi Mimo Re.


Emi iye at‘ agbara,
O ro ‘jo ekun ‘bukun Re
Le wa l‘ori.

6 p Fun idariji ese wa,


cr Ati fun ireti orun,
f Kil‘ ohun t‘a ba fifun O?
Onibu ore.

7 Owo ti a nna ofo ni,


Sugbpn eyi t‘a fi fun O,
O je isura tit‘ aye.
Onibu ore.

8 Ohun t‘a bun O, Oluwa


cr ‘Wo O san le pada fun wa,
f L‘ayo l‘a o ta O lore
Onibu ore.

9 Ni odo Re l‘a ti san wa,


Olorun Olodumare,
Je k‘ale ba O gbe titi;
Onibu ore
Amin.

663 8.6.8.6.8.8.8.6.
Ife ni Olorun. I Jn. 4:8.

1 f E wa k‘a jo jumo korin,


Ife ni Olorun
Orun, aye mu yin won wa
Ife ni Olorun!
Ki gbogbo okan ji kuro
Ninu ese ki won f‘ayo
Korin didun n‘tori Jesu,
Ife ni Olorun!

2 E so ni gbogbo agbaye
Ife ni Olorun!
N‘nu Krist‘ l‘ekun ‘rapada wa
Ife ni Olorun!
Eje Re le w‘ese wa nu,
Emi Re s‘oru wa d‘osan
O nto ‘kan wa lati so pe
lfe ni Olorun!

3 Ayo ni ipin wa nihin


Ife ni Olorun!
Okan wa nyo si ‘leri Re
Ife ni Olorun!
Orun at‘abo wa losan
O si mba wa gbe ni oru
On yo wa pelu wa titi
Ife ni Olorun!

4 Ni Sion lao tun korin yi


Ife ni Olorun!
ff Orin t‘yo ga soke julo
Ife ni Olorun!
Titi aye ainipekun
Pelu awon mimo loke
Orin wa to dun julp ni:
Ife ni Olorun!
Amin.

664 11.8.11.8.
Emi mi si yo si Olorun Olugbala mi.
Lk. 1:47.

1 mp Iwo niwaju eni t‘okan mi nyo


Ti mo npe nigba iponju,
‗Tunu mi l‘osan at‘ orin mi l‘oru
‘Reti mi at‘ igbala mi.

2 mp Nibo l‘o nko awon agutan Re lo,


Lati f'onje ife bo won,
Ese ti Un o fi sokun li ainidi
Tabi nikan rin l‘aginju?

3 mp O siju wo, opo angeli si yo,


Pupo si duro d‘oro Re;
O soro, ayeraye si gb‘ohun Re,
E korin iyin s'Oluwa.

4 mf Olugbala emi y‘o je Ipe Re,


Emi mo adun ohun Re;
Pa mi mo ‘tori Iwo ni gbogbo mi,
Un o ma yo ninu Re titi.
Amin.

665 8.8.8.6. & Ref.


Sugbon emi gbekele le O Oluwa;
Emi ni IWO ni Olorun mi. OD. 31:14.

1 mf Jesu, mo gbeke mi le O;
Ife Re si mi ti po to;
Iwo l‘agbara emi mi.
Eyi da mi loju.
f Tire nikan l‘emi,
Loni titi lae;
O feran mi Oluwa
Eyi da mi loju.

2 mf Ife o fi npase Tire,


Owo jeje l‘O fi nto ni;
Otito Re ni mo di mu,
Eyi da mi loju.

3 mf Momo pe un o wo ‘nu ogo,


Un o ma gbe ‘nu ile didan;
Igbagbo lilo y‘o dopin.
Eyi da mi loju.
Amin.

666 8.7.8.7.
Oluwa li Oluso-agutan mi.
OD. 23:1.

1 f J esu l‘Olus‘agutan mi,


Ore Eni ti ki ye!
Ko s‘ewu bi mo je Tire,
T‘On si je t‘emi titi.

2 f Nib‘ odo omi iye nsan


Nibe l‘O nm‘ okan mi lo,
Nibiti oko tutu nhu,
L‘O nf onje orun bo mi.

3 p Mo ti fi were sako lo,


cr N‘ife O si wa mi ri;
di L‘ejika Re l‘O gbe mi si,
f O f‘ayo mumi wa‘le.

4 p Nko beru ojiji iku,


cr B‘iwo bawa l‘odo mi;
Ogo Re ati opa Re
Awon l‘o ntu mi ninu.

5 mf Iwo te tabili fun mi;


‘Wo d‘ororo s‘ori mi;
A! ayo na ha ti PO to
Ti nt‘ odo Re wa ba mi?

6 f Be l‘ojo aye mi gbogbo


Ore Re ki o ye lae
Olus‘agutan, un o yin O
Ninu ile Re titi.
Amin.

667 9.6.9.8 & Ref


Sugbon On mo ona ti emi nto.
Jobu 23:10.

1 mf Mo l‘ore kan to wa nitosi'


L‘osan ati l‘oru,
O nfi oju Re SO mi titi
O mo ona ti emi ngba.
f O mo ona ti emi ngba,
O si npa mi mo l‘osan, loru
O nto mi li oruko Re,
O mo ona ti emi ngba.

2 mf Mo ni ore kan t‘o sunmo mi


Ko je ko mi sile;
Bi ona mi tile s‘okunkun
O mo ona ti emi ngba.

3 mf Mo l‘ore kan ti y‘o ma to mi


Tit‘ opin y‘o fi de
O nto mi titi un o fi d‘ade
O mo ona ti emi ngba.
Amin.

668 7.6.7.6. & Ref.


Mu okan iranse Re yo nitori Iwo Oluwa
ni mo gbe okan mi s 'oke si.
OD. 86:4.

1 f Okan ayo mi nko ‗rin


Ife Baba orun;
O ran opo ibukun,
B‘orun opo ibukun,
F Sugbon Jesu.........l‘O san julo......
(Jesu l‘o san ju)
Be ni Jesu ........ l‘O san julo.......
(Jesu l‘O san ju)
N‘nu gbogbo.......ti o yi.....ka
(Ninu gbogbo ayo ti o yika to yika)
Jesu nikan l‘O julo

2 mp B‘ayo miran gbogbo pin,


Ti ‗banuje si de,
mf Jesu yio pelu mi,
Onsi dara julo

3 mf Un o so fun elomiran
Itan or‘ofe Re;
Un o ma yo n‘nu isin Re
Titi un o r‘oju Re

4 f ‗Gba mo ba si ri ogo
Ninu odi Jasper;
Un o ko ‗rin irapada,
P‘Olugbala san ju.
Amin.
668 D.C.M
Awa feran Re; nitori On li o ko feran
I Jn. 4:19.

1 mf Jesu Oluwa a fe o,
‘Tori gbogbo ebun
Nt‘owo Re da lait‘ oke wa
B‘iri si gbogb‘ aye;
A yin O n‘tori ‘wonyi,
K‘ise fun won nikan,
Ni awon omo-odo Re
Se ngb‘ adura si O.

2 p Awa fe O, Olugbala,
‘Tori ‘gbat‘ a sako,
Iwo pe okan wa pada
Lati t‘ona iye;
‘Gba t‘a wa ninu okunkun,
Taa ri ninu ese,
cr ‘Wo ran imole Re si wa
Lati f‘ona han wa.

3 f Baba orun awa fe O,


Nitori ‘Wo fe wa
‘Wo ran Omo Re lati ku,
Ki awa le n‘iye;
‗Gbat‘a wa l‘abe ‘binu Re
'Wo fun wa n‘ireti;
cr Bi ese t‘a da ti po to
Be l‘o ndariji wa.
Amin.

670 7.7.7.D.
Nje nitorina, ara, ajigbese li awa.
Rom. 8:12.

1 mf ‘G bat‘ aye yi ba koja,


Ti orun re ba si wo
Ti aba wo ‘nu ogo.
T‘aboju wo ehin wa,
f Gbana, Oluwa, un o mo
di Bi ‘gbese mi ti po to.

2 f ‘Gba mo ba de‘b‘ite Re
L‘ewa ti ki se t‘emi,
‘Gba mo ri O b‘O ti ri,
Ti mo fe O l‘a fe tan;
‘Gbana Oluwa un o mo
di Bi ‘gbese mi ti po to.
3 f ‘Gba mba gbo orin orun,
T‘o ndun bi ohun ara,
Bi iro omi pupo;
p T‘o si ndun b‘ohunduru,
mf ‘Gbana Oluwa, un o mo
di Bi‘gbese mi ti po to.

4 mp Oluwa jo, je k‘a ri


Ojiji Re l‘aye yi,
p K‘a mo adun ‘dariji
Pelu iranwo Emi.
cr Ki ntile mo l‘aye yi
Die ninu ‘gbese mi.

5 mf Ore-ofe l‘o yan mi,


L‘o yo mi ninu ewu,
p Jesu l‘Olugbala mi,
Emi so mi di mimo;
cr K'O mi ki nfi han l‘aye,
Bi‘gbese mi ti PO to.
Amin

671 7.7.7.7
IWO fe mi bi? .Jn. 21:16.

1 mf Okan mi, Oluwa ni,


Jesu re ni, gb‘ oro Re.
Jesu nso, O mba o so,
p Pe, elese. 'wo fe mi?

2 mf ‘Gba t‘a de o, mo da O,
O gb‘ogbe, Mo wo o san,
Gb‘ o sako, Mo mu o bo;
Mo s‘okun re d‘imole.

3 Kike iya ha le pin


Si Omo re ti o bi?
di L‘otito, o le gbagbe,
cr Sugbon Em‘o ranti re:

4 mf Ife t‘Emi ki ye lae,


O ga rekoja orun;
O si jin ju okun lo,
f Ife alailegbe ni.

5 cr ‘WO fere r‘ogo Mi na,


‘Gb‘ ise ore-ofe tan;
‘WO O ba mi gunwa po
p Wi, elese ‘WO fe mi?
6 mp Olori aroye mi
Ni pe ife mi tutu;
cr Sugbon mo fe O Jesu,
f A! mba fe O ju yi!
Amin.

672 8.8.8.D.
E duro ninu ife mi.
Jn. 15:9.

1 mf Jesu Oluwa, Oba mi


Gb‘ohun mi nigbati mo npe
Gb‘ohun mi lati ‘bugbe Re
RO ‘jo ore-ofe sile
cr Oluwa mi, mo feran Re
Je ki nle ma feran Re si.

2 p Jesu mo ti jafara ju
cr Un o se le fe O, b‘o ti ye
Em‘ o se le gb‘ ogo Re ga;
Ati ewa oruko Re
Oluwa mi, mo feran Re
f Je ki nle ma feran Re si.

3 mf Jesu ki l‘o ri ninu mi


Ti ‘fe na fi po to bayi?
cr Ore Re si mi ti po to!
O ta gbogbo ero mi yo
f Oluwa mi, mo feran Re
Je ki nle ma feran Re si.

4 f Jesu ‘Wo o je orin mi,


Tire laya at'okan mi
Tire ni gbogbo ini mi
Olugbala, ‘Wo ni temi,
ff Oluwa mi, mo feran Re
Je ki nle ma feran Re si.
Amin.

673 6.4.6.4. & Ref.

Ma fi mi sile, beni ki o mase ko mi,


Olorun igbala mi. OD. 27:9.

1 mf M o nfe O n‘gbagbogbo,
Iwo Olore;
K‘o s‘ohun bi Tire
T‘o m‘alafia wa
ff Mo nfe O, A! mo nfe O.
Ni wakati gbogbo;
Bukun mi, Olugbala!
Mo wa s‘odo Re.

2 mf Mo nfe O n‘gbagbogbo;
Duro ti mi;
Idanwo ko n‘ipa
B‘o wa n‘tosi.

3 mf Mo nfe O n'gbagbogbo
L‘ayo, n‘ise,
Yara wa ba mi gbe,
Asan l‘aye.

4 mf Mo nfe O n‘gbagbogbo:
Ko mi n‘ife Re
Mu ileri Re se,
Si mi l‘ara.

5 mf Mo nfe O n‘gbagbogbo,
Eni Mimo,
Se mi n‘Tire toto
Omo ‘bukun!
Amin.

674 7.8.7.8.7.7.7.8.
Oluwa li Oluso-agutan mi.
OD. 23:1.

1 ‗Bolus‘agutan rere
mf Jesu nto wa, Jesu nto wa,
Si papa oko tutu,
Jesu nto wa, O nto wa
mp Bi‘kuku ba bo ona,
T‘ewu si yi agbo ka,
mf Ki y‘o je ki won sina,
Jesu nto wa, O nto wa.

2 mp Ninu wahala aye,


mf Jesu nto wa, Jesu nto wa,
Titi ao fi de oke,
Jesu nto wa, O nto wa.
O ti rin ona na ri,
O si nko agutan Re,
Lo sinu agbo t‘orun
Jesu nto wa, O nto wa.

3 mf Ninu ‘mole aye yi


Jesu nto wa, Jesu nto wa
L‘arin ogun at‘ija
Jesu nto wa, O nto wa
cr ‘Gbat‘ a ba d'odo Jordan
Nibiti ajo wa pin,
Y‘o si pin omi n‘iya.
Jesu nto wa, O nto wa.
Amin.

675 5.5.8.8.5.5.
Oluwa Olorun mi yo tan imole si
okunkun mi. OD. 18:28.

1 mf Jesu, ma to wa,
Tit‘ ao fi simi;
mp Bi ona wa ko tile dan
A o tele O l‘aifo ‘ya.
F‘OWO Re to wa,
S‘ilu Baba wa.

2 mp B‘ona ba l‘ewu,
B‘ota sunmo wa,
Maje k‘aigbagbo m‘eru wa,
Ki gbagbo on ‘reti ma ye,
f ‘Tor‘arin ota
L‘a nlo si le wa.

3 mp ‘Gbat‘ afe ‘tunu


Ninu ‘banuje,
‘Gbat‘ idanwo titun ba de
Oluwa fun wa ni suru;
f Fi ‘lu ni han wa
Ni b‘ekun ko si.

4 mf Jesu, ma to wa;
Tit‘ ao fi simi
Amona orun, toju wa
Dabobo wa, tu wa ninu,
Titi a O fi de
Ilu Baba wa
Amin

676 7.7.7. D.
On Opa mi mo ninu ago Re.
OD. 27:5

1 mp Apata ayeraye,
Se ibi isadi mi;
cr Je ki omi on eje
T'osan lati iha Re
Se iwosan f‘ese mi,
K'o si so mi di mimo.
2 mf K‘ise ise oWO mi
L‘o le mu ofin Re se,
B‘itara mi ko l‘are
T‘omije mi nsan titi,
Won ko to fun etutu
'Wo nikan l'o le gbala.

3 p Ko s'ohun ti mo mu wa,
Mo ro mo agbelebu;
Mo wa k‘od'aso bo mi,
Mo nwo O fun iranwo;
Mo wa sib'orisun ni,
cr We mi, Olugbala mi.

4 mp 'Gbati emi mi ba pin,


p T'iku ba p'oju mi de,
cr Ti mba lo s‘aye aimo,
Ki nri O n‘ite ‘dajo;
di Apata ayeraye
pp Se ibi isadi mi.
Amin.

677 8.7.8.7.8.7.
Iwo o fi imo Re to mi li ona ati nigbehin
IWO o gba mi sinu ogo OD. 73:24

1 mf Ma toju mi, Jehoha nla,


Ero l‘aye osi yi,
Emi ko l‘okun, Iwo ni
F‘owo agbara di mi mu,
mf Onje orun, onje orun,
Ma bo mi titi laelae.

2 cr S'ilekun isun ogo ni;


Orisun im'arale;
Je ki imole Re orun
Se amona mi jale;
Olugbala, Olugbala
f S'agbara at'asa mi.

3 p 'Gba mo ba de eba Jordan


Fokan eru mi bale,
cr Iwo t'o ti segun iku,
Mu mi gunle Kenan je;
f Orin iyin, Orin iyin
L'emi o fun O titi.
Amin.

678 7.7.7.7.
Awon aguntan mi kin yio segbe
Jn. 10:28

1 mf Tire laelae l'awa se


Baba, Olorun ife;
cr Je k‘aje Tire titi
L'aye yi, ati laelae.

2 mf Tire laelae, l'awa se


Ma toju wa la'ye yi;
‘Wo iye, Ona, Oto,
To wa si ilu orun.

3 p Tire laelae: Abukun


L'awon t‘ose simi won!
cr Olugbala, Ore wa,
Gba 'ja wa ja de opin

4 p Tire laelae:- Jesu pa


Awon agutan Re mo,
cr L'abe iso rere Re
Ni k'o pa gbogbo wa mo,

5 f Tire laelae:- Aini wa


Ni o je aniyan Re;
O ti f‘ese wa ji wa,
To wa si ibugbe Re.
Amin.

679 12.12.12.9. & Ref


Yio pa okan re mo. OD. 121:7

1 mf Mo mba rin, mo nba Jesu


Oba mi soro
Mo si ni ayo nin'orin ‘yin
Ti mo nko
f Bi mo ti gbekele si ni
Ojojumo
Ni o npa mi mo ninu 'fe Re
ff On pa mi mo ninu ife Re
Mo si mo, emi o ba loke
Yio so Tire titi'ojiji y'o fi lo
O npa mi mo ninu ife Re.

2 mf Mo ni ayo ninu Jesu,


Nko sina to
Igbadun ti o wa ninu ese lehin
f Nitori O nfun mi l‘ayo
L‘ojojumo O
Npa mi mo ninu ife Re.
3 mf Olurapada mi san ju
Gbogb‘ore lo.
O ti f‘ese mi ji, O si sure fun mi
f Mo si mo pe ao pade ni
Orun ‘simi
O npa mi mo ninu ife Re.
Amin

680 6.6.6.D
Jesu wipe: Iwo o ha fi emi re lele
nitori mi? Jn. 13:38

1 mf Mo f‘ara mi fun o,
Mo ku nitori re,
cr K‘o le jinde n‘n‘oku
p Mo f‘ara mi fun o
Kini ‗wo se fun Mi?

2 mp Mo f‘ojo aye mi,


Se wahala fun o
cr Ki iwo ba le mo
Adun ayeraye;
p Mo l‘opo' dun fun O.
O lo 'kan fun mi bi?

3 f Ile ti Baba mi,


At'ite ogo mi,
di Mo fi sile w‘aye,
Mo d'alarinkiri;
p Mo fi ‘le 'tori re,
Ki l'o fi'le fun mi?

4 Mo jiya po fun o,
Ti enu ko le so,
Mo jijakadi nla,
Tori igbala re;
mp Mo jiya po fun o,
O le jiya fun mi?

5 mf Mo mu igbala nla
Lat‘ ile Baba mi
cr Wa lati fifun o
Ati idariji
Mo m‘ebun wa fun o,
p Ki lo mu wa fun mi?

6 f Fi ara re fun Mi,


Fi aye re fun Mi,
Diju si nkan t'aye,
Si wo ohun t'orun;
Mo f‘ara mi fun o,
Si fara re fun Mi.
Amin.

681 7.7.7.7.D.
Emi fi ifeni ayeraye fe O.
Jer. 31:3.

1 mf Ifeni ayeraye,
L‘ore-ofe fi fe mi,
Emi Re lat‘oke wa
L‘o fi oye na ye mi,
Alafia didun ni
Ti ngbe mi kuro l‘aye,
Ife ti ko le tan ni,
Mo je Tire titi lae.

2 f Aye di orun fun mi,


O ndun si lojojumo,
Mo nri Krist‘ nibi gbogbo
Ti awon t‘aye ko ri,
Ninu orin t‘eye nko
Ninu itanna igbe,
Lat‘igba ti mo mo pe,
Mo je Tire titi lae.

3 f Ohun ti mba l‘eru


Ko tun ba mi l‘eru mo,
Labe iye-apa Re,
Nib‘ikok‘Oga ogo;
Nibe ni mo simi le;
Aniyan on ‘yemeji,
Ko duro l‘okan mi mo,
Mo je Tire titi lae.

4 f Tire laelac l‘emi se,


Tani y‘o ya wa n‘ipa?
Isimi wo lo to yi?
Fun okan ti Kristi ngbe;
B‘orun on aye koju,
Ti ogo re si parun,
T‘emi t'Olorun y‘o wa.
Mo je Tire titi lae.
Amin.

682 8.7.8.7.8.7.
Oju mi yio ma ba o lo, emi o si fun
o ni isimi. Eks. 33:14.

1 mp M a to wa Baba wa orun
Larin ‘danwo aye yi,
Fa wa mo k‘o si ma bo wa,
A ko n‘iranwo miran,
mf Sugbon gbogbo ‘bukun l‘ani
B'Olorun je Baba wa

2 mp Olugbala, dariji wa,


IWO sa m‘ailera wa,
cr ‘WO ti rin aye saju wa,
‘WO mo egbe inu re,
Bi alare, Eni- ‘kanu
N‘IWO l‘aginju yi ja.

3 f Emi Olorun, sokale,


F‘ayo orun k‘okan wa,
K‘ife dapo mo iya wa
At‘adun ti ki su ni,
B‘a ba pese fun wa bayi,
Ki lo le da wa lamu?
Amin.

683 9.7.9.7.9.8.9.7. & Ref


Lati fi oso fun won nipo eru, ororo
ayo nipo ofo, aso iyin nipo emi
ibanuje. Isa. 61:3.

1 mf Mo nkorin ife Olorun mi


Ti Emi Re ngbe‘nu mi,
Eni t‘O SO ekun ini dayo,
T‘o dari ese mi ji,
mp Bi ikuku tile su dede
mf Y‘o wa pelu mi ninu re,
O ntan imole s‘okukun mi
O si nm‘eru mi fuye,
O nso ibanuje mi d‘ayo
O nfun mi n‘ife ti ki sa,
f O ntan imole s‘okunkun mi
O si nm‘eru mi fuye

2 mf Mo nkorin ife Olugbala


Eni t‘o jiya fun mi
Nibi ikoko niwaju Re
O ja gbogbo ide mi
O mu onirobinuje yo
O nfun alare ni ‗simi,
O si nso omije di erin,
O nmu eru mi fuye

3 mf Mo nkorin ayo t‘ihinrere


Fun onirobinuje,
Ihinrere ayo at‘erin
Nibikibi ti mba lo,
Ti mbo aso ofo l‘ara wa
Ti nmu wa ko orin iyin,
f O tan imole s‘okunkun mi
o si nm‘eru mi fuye
Amin.

684 8.7.8.7.4.7.
Ki a si pa emi ati okan ati ara nyin mo
patapata li ailabuku.
I Tes. 5:23.

1 mf Orisun igbala kikun


Si sile fun gbogbo wa
Lat‘ Odo Olugbala wa
Lo nsan yi gbogb‘ aye ka;
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.

2 mf Iran ologo li eyi,


Isun iwenu ni o nsan,
cr O nwe gbogbo abawon nu,
Ti idalebi ese,
O nsan sibe,
Eje ti nwe mo laulau.

3 mf Isun ijinle ife Re


Nsan ni inu okan wa;
cr O nwe gbogbo ero aimo,
K‘a le wa lailabawon,
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.

4 mf Isun iye ainipekun,


Lati orun nsan si wa,
f Olorun dapo pelu wa,
Idapo t‘odun julo;
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.

5 f Eru‘banuje ti fo lo
Aniyan on ‘yemeji,
Igbagbo ko beru ola
Tor‘ Oluwa nsamona,
O nsan sibe,
Isun igbala kikun.
Amin.

685 L.M.
Awon orun nsoro Ogo Olorun.
OD. 19:1.

1 f Tire, Oluwa, li ogbon,


Ododo mbe li odo Re,
Sibe niwaju ite Re,
Anu lo da owo Re ro.

2 Alale nfi ife Re han,


Ororo nf‘ore nla Re han;
Ibinu Re ki tete ran,
Anu Re tan yi aye ka.

3 mf Baba, ore on ‘toju Re


L‘o fun wa n‘iye on ‘mole,
Ohun t‘a ni, ohun t‘a je,
Ebun atowo Re ni won.

4 mf Orisun ire, owo Re


L‘o nseri ‘bukun s‘ori wa,
L‘o nfonje on ayo fawon,
T‘o wa loke, n‘ile, l‘okun.

5 f N‘ipa Re ni gbogbo nkan wa


Agbara Re l‘o gbe won ro;
Papa awon t‘o ngb‘ ore Re
Ti won ntapa si ‘joba Re.

6 O pase ki orun k‘o ran,


Bakanna, sori gbogb‘ eda
Oro ojo ibukun Re
Sor‘ eni ‘re on buburu.

7 mp Awon t‘o gan agbara Re


Y‘o r‘ina ibinu Re;
mf Awon t‘o feran Re y‘o ni
Ayo ati ade didan.

8 f Tire, Oluwa, n‘ijoba,


Tire ni gbogbo agbara;
Bi gbogbo eda tile ku,
Sibe ogo Re y‘o ma tan.
Amin.

686 D.C.M.
E teti lele, ki e si wa sodo mi.
Isa. 55:3.

1 Mo gb‘ohun Jesu t‘o wipe,


Wa simi lodo Mi;
cr ‘Wo alare, gbe ori re
Le okan-aya Mi!
mp N‘nu are on ibinuje,
Ni mo to Jesu wa;
mf Lodo Re, mo r‘ibi-‘simi,
On si mu ‘nu mi dun.

2 Mo gb‘ohun Jesu to wipe,


cr Iwo ti ongbe ngbe,
Un o fomi‘ye fun o l‘ofe
Bere, mu, ko si ye!
Mo to Jesu wa, mo si mu
N‘nu omi iye na;
mf Okan mi tutu, o soji,
Mo d‘alaye n‘nu Re

3 Mo gb‘ohun Jesu to wipe,


cr Mole aye l‘Emi;
Wo mi, orun re yo si la,
Ojo re yo dara
Mo wa Jesu n‘nu Re mo ri
‘Rawo at‘Orun mi;
N‘nu‘ mole Re l‘emi yo pin
Tit‘ajo mi yo pin.
Amin

687 10.10.11.11
Kili emi o san fun Oluwa, nitori
gbogbo ore re si mi. OD. 116:12.

1 mf Kini uno fi yin Olugbala mi,


Eni oloto t‘o po l‘or‘-ofe,
T‘o le fi igbala on irapada
F‘awon onigbagbo t‘o gb‘okan won l‘E?

2 f Ayo eni t‘a dande ti PO to,


Awon eniyan na t‘o le yo n‘nu Re!
Ayo won ni lati rin n‘nu ‘mole Re,
Sibe nwon nso nipa or‘-ofe Jesu.

3 f Won nyo n‘nu oko Re lojojumo;


Won nfododo Re s‘ohun eto won;
Eje Re we won, n‘nu ododo Re,
Laifoya ni nwon o yoju s‘Olorun.

4 F IWO ni fuja, ogo, ipa won:


Emi si nreti igba ayo na,
Ti un o di atunbi, ti un o d‘alaye,
Ojo ‘gbala ti y‘o gb‘ori mi soke.
5 f Jesu Oluwa, li abo fun mi;
Ko s‘eni t‘o le ja mi lodo Re;
Y‘o se ohun gbogbo n‘tor‘ O feran mi
Olugbala mi y‘o SO mi di otun.

6 ff O daju, Jesu, un o ri ‘bukun Re,


Asiri Re si fere han fun mi;
Emi y‘o ri ayo dipo ‘banuje;
Un o n‘ipin n‘nu ayo awon t‘O gbagbo.
Amin.

688 8.7.8.7.D.
Ko si enikan ti o ni ife ti o tobiju eyi lo,
pe enikan fi emi re lele nitori
awon ore re. Jn. 15:13.

1 mf M o l‘Ore kan, ife Re PO!


O fe mi k‘emi t‘o m‘O;
cr Okun ife l‘O fi fa mi,
O si demi mo ‘ra Re;
Koko ‘fe Re t‘a ko le tu,
Lo mo okan mi sibe;
f Mo je Tire, On je temi,
Lae ati titi laelae.

2 mf Mo l‘Ore kan, ife Re po


O ku lati gba mi la;
Cr Iye nikan ko l‘O fun mi
O fi ara Re ji mi,
Nko ni p‘ohun kan ni temi
Un o pamo f‘Olufunmi;
f Okan, agbara, emi mi
Tire, ni titi laelae

3 mf Mo l‘Ore kan, ife Re po


Gbogb‘ agbara l‘a fi fun
K‘ O le so mi li ajo mi,
K‘ O si mu mi de orun
F Ogo ailopin ntan ‗mole,
Lati fun mi li okun;
Un o sora, un o sise un o ja,
Lehin na, un o simi lae

4 mf Mo l‘Ore kan, ife Re po,


Oniyonu, Oloto!
Olugbimo at‘Amona,
Alabo t‘o lagbara!
cr Kini ‗ba le ya mi lodo
Eni fe mi po to yi;
Iye, iku? Aye, egbe?
f Beko! Mo je Tire lae.
Amin.

689 C.M.
Oluwa, iwo ni mo gbe okan mi
soke si. OD. 25:1.

1 mp Baba, mo gb‘okan mi si O
‘WO ni mo gbekele;
Cr Mo mo daju pe lodo Re
L‘ebun pipe ti wa.

2 mf Tire nikan l‘anu, ore,


Agbara on Ogbon;
Li aisi Emi Omo Re
A ko le se ‘re kan.

3 mp A ko s‘oro rere kan,


A ko le ro ‘re kan,
B‘Iwo ko ba sure fun wa
N‘tori Oluwa wa.

4 O f‘eje Re ra or‘-ofe,
Agbara eje na
L‘o se ‗ranwo fun iran wa,
Ati fun mi pelu

5 Gbogbo ise rere t‘a nse,


Iwo li O nse won;
f Tire n‘iyin gbogbo ero
At‘oro rere adura

6 Lat‘odo Re, nipa Jesu


L‘a gb‘ase adura;
N‘nu eni ti a mbe laye;
Olodumare wa!
Amin.

690 8.7.87.D.
Iwo li o da mi ni ide ninu iponju.
OD. 4:1.

1 mf Baba orun, Wo l‘o mu wa


D‘ojo oni f‘alafia,
Pele l‘Onto isise wa,
T‘O si nf‘iso Re so wa,
‘Wo Ore at‘ Amona wa,
A fe fi ope fun O;
A o se le yin O b‘o ti ye
Fun ‘fe Re ti ki pada?

2 mf Ni gbogbo igba t‘o koja


L‘a nri anu gba lotun,
Itoju on iseun-ife
Ko fi igba kan jin na.
Ife ati aba orun;
Mba wa gbe tosan-toru
Ibukun t‘a ko le siro
Ntan imole s‘ona wa.

3 mp N‘nu ‘danwo nla l‘a ti ko


Iji ‘ponju ti lu wa;
Idamu ti sokun bo wa
Tobe t‘a ko fi ri O;
mf Sibe ife Re ko ko wa
Sibe n‘nu ‘banuje wa,
Iranwo t‘a nse f‘ara wa
Nipa agbara Re ni.

4 pp Opo awon olufe wa


Ti de opin ajo won;
Ara, omo ati ore.
Nwonaa lati pade wa
cr Nigba t'ajo wa ba pari,
Ti a si se alaisi,
mf Baba, mu wa la okun ja
Sinu ‘mole ailopin.
Amin.

691 7.6.7.6.8.8. & Ref.


Anu se e. Lk. 10:33.

1 mf Ife l‘o fi wa emi


Ti eru ese npa,
O gbe mi s‘ejika Re
Pada bowa s‘agbo
F Angeli nfi ayo korin
Pelu awon ogun orun
ff A! Ife t‘o wa mi,
A! Eje t‘o ra mi
Suru pelu ore-ofe Re
T‘o fa mi pada bo wa s‘agbo!

2 mp Mo gbogbe, mo fere ku
O tu ororo si;
O so fun mi jeje pe:
pp "Temi ni iwo se!‖
f Nko gb‘ohun t‘o dun to ‘yi ri
O mu okan are mi yo.
3 O f‘apa iso han mi,
N‘tori mi l‘O jiya;
A de li ade egun
Lati fi se esin;
Nko m‘ohun t‘O ri l‘ara mi
T‘o fi jiya po be fun mi.

4 mp Mo joko niwaju Re,


N‘nu ‘mole oju Re;
Mo si nfi iyanu nla
Ranti ibukun Re;
f Ayeraye fere ma to
Lati fi korin iyin Re.

5 B‘akoko ti nkpja lo
N‘isimi pipe de;
f Mo nreti owuro ni
Ti o dara julo,
‘Gba‘ On y‘o pe wa sodo Re
B‘iyawo Re, lailaba won.
Amin.

692 8.7.8.7.D.
Eniti o ba fe Olorun, o fe arakunrin
re. I Jn. 4:21.

1 mf Ara, e je k‘a jumo rin


N‘ife on alafia;
A ha le ma tun bere pe,
O to k‘a ba f‘ija mo?
p Ni repo ni irepo
l‘ayo, ife, y‘o fi po

2 f B‘a ti nrin lo sile, je k‘a


Ran ‘ra wa lowo lona;
Ota ka wa nibi gbogbo;
mp S‘ona gbogbo l‘a dekun,
Ise wa ni, Ise wa ni,
K‘a ma ran ‘ra wa l‘eru.

3 Nigbat‘ a r‘ohun Baba se,


T‘o ti fi ji, t‘o nfiji,
mp Ara, ko to k‘awa k‘o ko
Lati ma fija sile?
K‘a mu kuro, kra mu kuro.
Ohun ‘ba mu ‘binu wa.

4 f K‘a gb‘omonikeji wa ga,


Ju b‘a ba ti gbe‘ra wa;
K'a fi keta gbogbo sile,
K‘okan wa si kun fun ‘fe;
mf Yio ro wa, Yio ro wa,
B‘a wa n‘ireo l‘aye.
Amin.

693 S.M.
Nkan wonyi ni mo palase fun nyin
pe ki enyin ki o fe omonikeji nyin.
Jn. 15:17.

1 mf ‗Fe enikejire,‖
Ase Oluwa ni;
O sa fara Re sapere,
Ni fife t‘O fe wa.

2 mf ―Fe enikeji re‖


N‘ire tabi n‘ija;
O ko wa pe k‘a f‘ota wa,
K‘a fore san ibi.

3 mf ―Fe enikejire,‖
cr Oluwa nke tantan;
f O ye ki gbogbo wa mura,
K‘a f enikeji wa.

4 mf ―Fe enikejire,‖
At‘ aladugbo re,
Pelu gbogb‘ eni yi o ka,
At‘ota re pelu.

5 K‘a f enikeji wa,


Bi Jesu ti fe wa
Jesu sa fe awon ota Re,
O si sure fun won.
Amin.

694 S.M.
Ema ru eru omonikeji nyin. Gal. 6:2.

1 mf Bukun ni fun ohun,


T‘o de wa po n‘nu ‘fe;
Idapo awon olufe,
Dabi ijo t‘orun.

2 mp Niwaju ‘te Baba,


Li awa ngbadura;
Okan n‘ireti at‘eru,
Ati ni itunu.
3 p Awa mb‘ara wa pin
Ninu wahala wa;
Awa si mb‘ara wa sokun
Ninu ‘banuje wa.

4 mf Nigbat‘ a ba pinya,
Inu wa a baje;
Sibe okan wa y‘o j‘okan
N‘ireti ipade.
Amin.

695 C.M.
Ife tire ni ki a se, bi ti orun, beni
li aiye. Mat. 6:10.

1 f Jesu, lye, Oto, Ona,


Eni ti mo gbagbo,
B‘O ti ko mi, mo ngbadura,
Mo nreti ki nri-gba.

2 mf Jeki nma se ‘fe Re laye,


Bi won ti nse l‘orun,
Awon ti nri O lori ‘te
Ti nsogo n‘nu 'fe Re

3 Mo ntoro ore ofe Re.


Lati le se 'fe Re.
B‘awon angel‘ ti nr‘oju Re.
Ti nmu oro Re se.

4 di Dajudaju, em‘ elese


Y‘o sin O laifoya;
mf Okan mi ko lati tun gba
Adura etan mi.

5 ‘Gbat‘ O ba s‘ise gbogbo tan,


Emi y‘o mo n‘inu,
cr Nki o dese l‘ohunkohun;
N‘tori angel‘ ki se

6 f Emi ki o tun ya O mo,


Nki o si da O mo,
Emi y‘o fe O laisetan;
N‘tori angel‘ ni fe.

7 Un o ma se ife mimo Re
Em‘ otos‘ elese,
‘Gba m‘ba fe O tokan-tokan,
Un o ma p‘ofin Re mo
8 Or‘ofe nipa atunse
Li a o fifun mi,
Un o si ma se‘fe Re
B‘angel‘ ti n se.
Amin.

696 7.7.7.7
Emi ko ri ese lowo okunrin yi
Lk. 23:4.

1 mf Jesu alail‘ abawon,


O ti feje Re ra mi
Nko nani ohunkohun,
Lehin agbelebu Re

2 mf Tire nikan ni mo je
O fun mi l‘ekun ayo,
Lati isisyi lo
Iyin Re ni un o ma wa

3 mf Je ki ngbe itiju Re,


Ki nje wo oruko Re,
Ki nwa lati tele O
p Bi mo tile nri egan

4 f ‘Gbat‘ O bayo n‘nu ogo,


Ti mo de ile l‘oke,
Ahon mi yo kigbe pe,
Tire nikan ni mo je.
Amin.

697 L.M.
Awa fe e, nitori On tete fe wa.
1 Jn. 4:19.

1f Awa ko orin ife Re


Obangiji Oba Ogo;
Ko s'ohun ti lalasi Re,
Ola Re ko si nipekun.

2 f N‘nu ife lo s‘eda aye,


O da eniyan sinu re;
Lati inu s‘akoso gbogbo;
ff E korin ‘fe Eleda wa.

3 f Lojojumo l‘O ntoju wa,


O si mbo, O si nsike wa;
Beni ko gba nkan lowo wa,
ff Korin ‘yin s‘Onibu ore.
4 p O ri wa ninu okunkun,
Pe, a ko mo ojubo re;
N‘if'e O fi ona han wa;
ff E korin ife Olore!

5 N‘ife O fi Jesu fun wa,


Omo-bibi Re kan soso;
p Owa ra wa lowo ese;
ff A yin‘fe Re Olugbala!

6 Ife Re ran oro Re wa,


Ife Re l‘o si wa leti,
Ife Re si mu wa duro;
ff E korin ore-ofe Re

7 Gbogbo eda kun fun‘fe Re


Oluwa wa, Oba aye;
Ff Gbogbo agbaye, e gberin,
Orin ife Olorun wa.
Amin.

698 S.M.
Nigbati nwon ko si ni ti nwon o san,
Tinu-tinu li o dariji awon mejeji.
Lk. 7:42.

1 mf O fun mi l‘edidi,
Gbese nla ti mo je
B‘o ti fun mi, O si rerin
p Pe; Mase gbagbe Mi.

2 mf O fun mi l‘edidi
O san igbese na
B‘o ti fun mi O si rerin
Wipe; ma ranti Mi!

3 mf Un o p‘edidi na mo
B‘igbese tile tan;
O nso ife Eni t‘o san
Igbese na fun mi.

4 f Mo wo mo si rerin
p Mo tun wo mo sokun
mf Eri ife Re si mi ni
Un o toju re titi.

5 Ki tun s‘edidi mo,


Sugbon iranti ni!
f Pe gbogbo igbese mi ni
Imanueli san.
Amin.

699 8.7.8.7.D.
Eniti ojoko ni ibi ikoko Oga-ogo ni
yio ma gbe a be ojiji Olodumare.
OD. 91:1.

1 mf N‘nu ojiji Oga-ogo


cr L‘abo mi y‘o wa titi;
N‘tori oju Re ti ki sun
F Nso mi n‘gba gbogbo sibe
f Emi ngbe ninu ojiji
ti Oba awon oba;
O f‘iye-apa Re bo mi,
Nibe ni mo si simi

2 mf N‘nu ojiji Oga-ogo


f Mo bo loW‘ eru gbogbo
N‘tori apa Re gba mi mu,
O si yi mi kakiri.

3 mf N ‘nu ojiji Oga-ogo


F Ibi kan kole de ‗be;
Krist‘ n‘ireti, asa, abo,
Olugbala, gbogbo mi.
Amin

700 7.6.7.6.D.
Olorun fe araiye to be ge ti O fi
Omo bibi re kan soso fun ni.
Jn. 3:16.

1 f Olorun fe araye,
O fe tobee ge,
T‘O ran Omo Re w‘aye
T‘O ku fun elese;
Olorun ti mo tele
p Pe, emi o se si
Ofin ati ife Re;
IWO ha fe Mi bi?

2 Loto, Olorun fe mi,


Ani-ani ko si,
Awon t‘o yipada si,
Igbala ni won ri:
pp Wo! Jesu Kristi jiya,
Igi l‘a kan a mo:
Wo! eje Re ti o nsan,
Wo! ro! Ma d‘ese mo.
3 p Jesu s‘agbelebu Re,
Un o kan ese mi mo;
Labe agbelebu Re,
Un o we ese mi nu;
mf Nigbat‘ emi o ri O,
Ni orun rere Re,
ff Nki yio dekun yin O,
F‘ogo at‘ola Re.
Amin.

701 8.8.8.D
Ngo fe O Oluwa agbara mi.
OD. 18:1

1 f Un o feran Re, ‘Wo odi mi,


Un o feran Re, ‘Wo ayo mi
Un o feran Repatapata,
Iwo nikan, pelu ‘se Re
cr Un o feran Re, tit‘ okan mi,
Y‘o fi kun fun ife rere.

2 mf Iwo orun ti a ko da,


Mo s‘ope fun imole Re
Mo s‘ope t‘O segun ota
T‘O wo ogbe okan mi san
Mo s‘ope n‘tori ohun Re
Nmu okan mi yo ninu Re

3 mf Gbe mi ro n‘nu ‘re ije yi


Ma je k‘emi tun sako lo;
cr Fun ese mi l‘okun, lati
Ma te siwaju l‘ona Re,
ff ‘Wo Oluwa, Alagbara
F‘imole Re te mi lorun.

4 f Un o feran Re, ‘WO ade mi


Un o feran Re, Oluwa mi;
di Un o feran Re nigba gbogbo,
L‘ojo ibi, l‘ojo ire,
p ‘Gbati ojo iku, ba de,
f Un o feran Re titi laelae.
Amin

702 C.M.
Ki Kristi ki o le ma gbe inu okan
nyin nipa igbagbo. Efe. 3:17.

1 mf Jesu, kiki ironu Re


Fi ayo kun okan;
Sugbon k‘a ri O l‘o dun ju,
K‘a simi l‘odo Re

2 Enu ko so, eti ko gbo,


Ko t‘okan jade ri:
Oko t‘o s‘owon, t‘o dun bi
Ti Jesu Oluwa.

3 p Ireti okan ti nkanu,


Ayo onirele
cr O seun f‘awon ti nwa O
f Awon t‘o ri O yo.

4 f Ayo won, enu ko le so


Eda ko le rohin;
Ife Jesu b‘o ti po to
Awon Tire l‘o mo.

5 f Jesu, ‘WO ma je ayo wa


‘Wo sa ni ere wa
Ma je ogo wa nisiyi
Ati titi laelae.
Amin.

703 C.M.
Beni Oluwa, iwo mo pe, mo feran
Re. Jn. 21:15.

1 mf Olugbala mi, ife Re


Ha tobi be si mi?
Wo, mo fife mi, okan mi,
At‘aya mi fun O.

2 Mo fe O nitori ‘toye
Ti mo ri ninu Re,
p Mo fe O nitori iya
T‘o kun fun iyonu.

3 f Bi iwo ti je Olorun
T‘a f‘ogo de lade;
di Iwo ko ko awo eeyan
O f‘ara da iya.

4 p ‘Wo je k‘abi O l‘eniyan,


Sugbon ‘Wo ko l‘ese;
cr K‘a wa le ri b‘lwo ti ri,
K‘a le se b‘O ti se.

5 f K‘a dabi Re ninu ife;


L‘ewa ore-ofe;
cr B‘a ti nwoju Re, k‘ama lo
L‘at‘ ogo de ogo.
Amin

704 C.M.
Oruko kan ti u bori gbogbo oruko. Fili. 2:9.

1 mf Oruko kun mbe ti mo fe


Mo fe ma korin Re;
f Iro didun ni l'eti mi,
Oruko didun ni.

2 mf O so ife Olugbala
T‘O ku lati ra mi,
O so eje Re ‘yebiye
Etutu elese

3 cr O so ti iyonu Baba,
Ti O ni s‘Omo Re,
O m‘ara mi ya, lati la
Aginju aye ja.

4 f Jesu, oruko ti'mo fe,


T‘o si dun l‘eti mi;
Ko s‘eni mimo kan l‘aye
T‘o mo b‘o ti po to.

5 Oruko yi j‘orun didun


L‘ona egun t‘a nrin;
Yio tun ona yangi se
T‘o lo s‘od‘Olorun.

6 Nibe pelu awon mimo


Ti won bo nin‘ ese
f Emi o korin titun ni
T‘ife Jesu si mi.
Amin.

705 6.4.6.4.6.6.4
Beni Oluwa: IWO mope, mofe O.
Jn. 21:15.

1 f Ki nfe O si Kristi,
Ki nfe O si!
Gb‘adura ti mo ngba
L‘or‘ ekun mi;
p Eyi ni ebe mi;
Ki nfe O si Kristi:
Ki nfe O si,
Ki nfe O si.
2 f L‘ekan ohun aye
Ni mo ntoro;
Nisiyi, ‘WO nikan
Ni emi nwa;
f Eyi l‘adurami:
Ki nfe O si Kristi,
Ki nfe O si,
Ki nfe O si.

3 p Je ki ‘banuje de
At‘irora;
Didun l‘o jise Re
At‘ise won;
f ‘Gba won mba mi korin:
Ki nfe O si Kristi,
Ki nfe O si,
Ki nfe O si.

4 p Nje, opin emi mi


Y'o jiyin Re,
Eyi y‘o je oro
Ikehin mi;
f Adura mi y‘o je:
Ki nfe O si Kristi,
ff Ki nfe O si,
Ki nfe O si.
Amin.

706 8.8.8.D.
Oluwa, ko mi ni ilana Re.
OD. 119:64.

1 mf Jesu, ailopin ife Re


Ko si b‘a ti le royin re,
S‘okan ope mi ni Tire,
K‘O si nikan joba nibe!
Tire ni mi patapata
Ma mu ‘fe mi gbona titi.

2 mf Mase je ki ohunkohun
Gba mi l‘okan ju ‘fe Re lo:
K‘ife Re gbe gbogb‘ okan mi!
K‘o j‘ayo; ‘sura, ade mi;
Mu ‘fekufe jinna si mi;
K‘ero, ise mi je t‘ife

3 cr Itansan ‘fe, fun mi l‘ayo!


Irora sa niwaju Re,
Aniyan, ‘banuje y‘o lo
Nibi ‘tansan ‘wosan Re de;
Jesu, jowo ma je ki nfe
Ohun-kohun kan leyin Re.

4 f Je ki nma lepa ife yi


At‘ere giga, lai s‘are;
So ina mimo yi d‘otun
N‘nu emi mi lojojumo;
K‘ajo mi l‘osan l‘oru je
Lati so ‗sura owo na.
Amin.

707 C.M.
Oluwa ni Oluso-agutan mi, emi ki yio
se alaini. OD. 23: 1

1 f Jesu l‘Oluso-aguntan mi
Emi ki o salaini;
Nib‘ odo at‘oko tutu
L‘o nfowo Re to mi.

2 f O mu k‘okan mi tun soji,


O nto isise mi:
Ni ipa ona ododo,
N‘tori oruko Re

3 p Bi mo nrin nin‘ojiji‘ku
mf Emi ki o beru;
WO mbe pelu mi, opa Re
Y‘o ma tu mi n‘ inu.

4 mf IWO te tabili fun mi


Loj‘ awon ota mi;
IWO d‘ororo sori mi;
Ago mi kun, o nse

5 f Ire at‘ anu Re nto mi


Ni gbogbo aye mi;
Un o si fi ile Olorun
Se‘bugbe mi laelae.
Amin.

708 D.L.M.
Nitori Emi Oluwa Olorun re yo di
owo otun re mu. Isa. 41:13.

1 f O nto mi lo ero ‘bukun,


Oro t‘orun tu mi ninu,
Ohun ti o wu k‘emi je
Sibe Olorun nto mi lo
ff O nto mi lo, O nto mi lo
Owo Re l‘o fi n to mi lo
L‘otito ni mo fe te l'E
Nitoriti O nto mi lo

2 mp Nigba miran t‘iponju wa


Nigba miran l‘ogba Eden‘
L‘eba odo, l‘okun ‘poju
f Sibe. Olorun nto mo lo.

3 f Oluwa mo d‘owo Re mu
Nko ni kun, nko ni banuje,
F‘ohun y‘o wu ti mo le ri
Niwon t‘Olorun mi nto mi.

4 Nigba‘se mi l‘aye ba pin


T‘or‘-ofe fun mi ni ‘segun
Emi ko ni beru iku
Niwon t‘Olorun mi nto mi.
Amin.

709 S.M.
Fi ibukun fun Oluwa, iwo okan mi,
ma si se gbagbe gbogbo ore Re
OD. 103:2.

1 mf F‘ibukun f‘Oluwa
Yin ore-ofe Re.
f Gbogb‘ ohun ti mbe ninu mi
Yin oko Re mimo

2 mf F‘ibukun f‘Oluwa
Fun opo anu Re,
Mase gbagbe lati dupe
Inu‘re Re si O.

3 cr Loto, O mba ni wi
K‘ise nigba gbogbo,
O nse suru, O si nlora
Lati binu si wa.

4 cr O f‘ese re ji O
O lora emi re,
O wo gbogbo arun re san,
O gba o lowo ‘ku.

5 cr O d‘aso‘ fe bo o,
Oro Re gbe o ro,
O SO agbara re d‘otun
Bi ti eye idi,
6 f Yin Oruko Re nla,
Eni t‘O wo o san,
T‘iseun ‘fe Re de o l‘ade,
F‘ibukun f‘Oluwa.
Amin.

710 7.9.7.9. & Ref.


Fa mi, awa o sare to O
Orin Sol. 1:4.

1 mf Olugbala mi owon,
Un o ma sunmo, sunmo O titi;
Fi eje ‘yebiye Re.
Fa mi mora, mora sunmo O;
cr Jojumo, ‘gba-kugba,
Je ki nmo agbara Re,
Ki fife t‘Iwo fe mi,
Fa mi mora, mora, sunmo O

2 N‘nu aye ti nkoja yi


di Rora to mi sinu ife Re,
mf Emi ki y‘o si sina
Bi IWO funra re ba nto mi.

3 cr Je ki ntubo feran Re
N‘igba die un o lo l‘aye;
Ki nfe O titi dopin,
Titi aye ti ko nipekun.
Amin.

711 8.8.6.D.
Emi ogbon, ati oye
Isa. 11:2.

1 cr Emi ogbon, to oju wa


Kuro ninu asan aye,
S‘oto on ‘fe orun;
Emi oye ti o daju,
Fi imole orun fun wa
Lati wa nkan toke.

2 cr Emi ‘moran, s‘Amona wa


F‘ijakadi aye ko wa.
K‘a gba adet‘orun;
mf Emi‘gboya, k‘agbara Re
Ran wa lowo nigba ‘danwo
Pa wa mo lailese

3 cr Emi imo, to ese wa


Li ona Re ti ko l‘ewu
T‘awon angel‘ti rin;
Nibi t‘Iwo Oluto wa,
mp Iwo Emi ifokansin,
Mu wa sunm‘ Olorun.

4 cr Sunmo wa l‘ojo aye wa,


Emi iberu Olorun,
N‘ikoko aya wa;
F‘owo t‘o ye kun okan wa
Lati sin ife mimo Re,
T‘o l‘ododo julo

5 mf Ma to wa lo l‘alafia,
Sinu iye ainipekun,
cr K‘a jere giga na;
K‘ajaogun aye wa yi,
Nipa agbara Re mimo.
K‘a si ba Krist‘joba.
Amin.

712 8.8.8.D.
Baba mi, iwo ni ayanfe igba ewe mi.
Jer. 3:4.

1 cr Oluwa, n‘igba ewe wa,


A mbe O, ma s‘Oluto wa;
Sunmo wa si fa wa lowo,
To wa lo si ‘le rere na;
Pelu ‘mole l‘osan l‘oru,
Wa pelu wa l‘on‘ajo wa.

2 mp Awa nlo sinu aginju,


Ao le sairi etan Esu;
A ko lokun, ija si le,
mf Sibe ao segun n‘ipa Re
Titi ao bori gbogb‘ ota
T‘ ao fi ounje orun bo wa.

3 mp ‘Gba ‘banuje on wahala


Mu wa sunmo O, Oluwa;
mf ‘Gba ti ayo toyi waka
Mu k‘okan wa kun fun ope,
cr ‘Gbat‘ irin-ajo wa ba pin,
Gba wa sinu isimi Re

4 mf M‘ese wa duro l‘ona Re,


Ma si jek‘ okan wa sako,
Fi suru se amona wa,
Pa wa mo n‘nu ewu gbogbo
Bu Iya on aini wa ku,
F‘ese wa mule de opin.
Amin

713 8.7.8.7.
Emi mo pe, ninu mi ko si nkan
to dara. Rom. 7:18.

1 mf Baba orun! emi fe wa


N‘iwa mimo l‘ododo:
Sugbon ife eran ara
Ntan mi je nigbagbogbo.

2 p Alailera ni emi se,


Emi mi at‘ ara mi;
Ese ‘gbagbogbo ti mo nda
Wo mi l‘orun b‘eru nla.

3 Ofin kan mbe li okan mi


‘WO papa l‘o fi sibe;
‘Tori eyi ni mo fi fe
Tele ‘fe at‘ ase Re

4 Sibe bi mo fe se rere,
Lojukanna mo sina;
Rere l‘oro Re i ma so;
Buburu l‘emi si nse.

5 Nigba pupo ni mo njowo


Ara mi fun idanwo;
Bi a tile nkilo fun mi
Lati gafara f‘ese

6 Baba orun, Iwo nikan


L‘o to lati gba mi la;
Olugbala ti o ti ran,
On na ni un o gbamora.
Amin.

714 S.M.
E je ki a maa sore fun gbogbo
eniyan. Gal 6:10.

1 f Ohun t‘a fi fun O Tire ni, Oluwa;


Gbogbo ohun ti a si ni;
Owo Re l‘o tiwa.

2 mf Je k‘a gba ebun Re


Bi iriju rere;
Bi o si ti nbukun wa to,
Be l‘a o fi fun O
3 p Opo ni ise n se,
Ti won ko r‘ounje je
Opo l‘o si ti sako lo,
Kuro l‘agbo Jesu.

4 cr K‘a ma tu ni ninu,
K‘a ma re ni ‘lekun,
K‘a ma bo alaini baba
N‘ise t‘a ba ma se.

5 mf K‘a tu onde sile,


K‘a mu asako bo,
Ka ko ni l‘ona Olorun,
B‘iwa Kristi l‘o ri.

6 cr A gba oro Re gbo,


di Busi igbagbo wa,
f Ohun t‘a se fun eni Re,
Jesu, ase fun O.
Amin.

715 C.M.
E ma a ru eru omonikeji yin.
Gal. 6:2.

1 mf ‘Wo orisun ohun rere,


Awa fe se ‘fe Re,
Ohun wo l‘a le fi fun O,
Oba gbogbo aye?

2 L‘aye yi, ‘Wo ni otosi


cr T‘o je eniyan Re;
Oruko wo n‘lwo njewo,
Niwaju Baba Re.

3 mp ‘Gba won ba nke n‘inira won


Ohun Re l‘awa ngbo;
Ki O pese fun aini won,
K‘O da won l‘ara ya.

4 Lara awon otosi Re,


L‘oju ife Re wa;
‘Gba ba si nse itoju won,
A nse si O, Baba.
Amin

716 10.10.
Nigbagbogbo li enyin sa ni talaka
pelu yin. Mk. 14:7.
1 mf Mo nlo, talaka Mi mbe l‘odo yin,
E le ma s‘ore fun won b‘e ti nfe,

2 mf Eyi ni ogun t‘Olugbala wa


Fi sile f‘awon Tire k‘o to lo.

3 Wura on jufu ko, otosi ni;


K‘a ma ran won l‘owo nitori Re.

4 cr Eru nla ko, ogun t‘o l‘oro ni;


Ti n f‘ilopo ‘bukun feni ntore.

5 mp Tiwa ki ‘se na bi? L‘ojude wa


KO ni talaka at‘ asagbe wa?

6 Ohun irora awon t‘iya nje


Ko ha nke si wa lati f‘anu han?

7 Okan t‘o gb‘ogbe, okan ti n sise


Ekun opo, at‘alaini baba.

8 cr On t‘O fara Re fun wa, si ti fi


Etu orun f‘awa iranse Re.

9 Ko s‘otosi kan ti ko le sajo


F‘eni tosi ju lo, agbara ni.

10 Isin mimo ailabawon l‘eyi,


Ti Baba mbere lowo gbogbo wa.
Amin.

717 11.11.11.11.
On le pa ohun ti mo fe le lowo mo.
II Tim. 1:12.

1 mf Jesu, emi o fi okan mi fun O


mp Mo jebi mo gbe, Sugbon ‘Wo
le gba mi
cr L‘aye ati l‘orun ko s‘eni bi Re,
p IWO ku felese, f‘emi na pelu.

2 mf Jesu, mo le simi le oruko Re.


Ti angeli wa so, lojo Ibi Re,
p Eyi t‘a ko t‘o han lor‘ agbelebu,
cr Ti elese si ka, won si teriba.

3 mf Jesu, emi ko le sai gbekele O,


Ise Re l‘aye kun fanu at‘ife,
Mo Elese yi O ka, adete ri O,
Ko s‘eni buruju, ti ‘Wo ko le gba.

4 mf Jesu, mo le gbeke mi le oro Re,


Bi nko tile gbo ohun anu Re ri,
‘Gbat‘ Emi Re nko ni, o ti dun po to,
di Ki nsa fi' barale k‘eko lese Re

5 f Jesu toto-toto mo gbeke le O,


Enikeni t‘o wa, ‘WO ki o ta nu,
ff Oto ni ‘leri Re, Owon l‘eje Re
Wonyi ni gbala mi, ‘WO l‘Olorun mi.
Amin.

718 8.8.8.9.D.
Gbe agbelebu re ki o si ma to
mi lehin. Mat. 16:24.

1 cr Mo gbo Olugbala mi npe,


Mo gbo Olugbala mi npe;
Mo gbo Olugbala mi npe,
―Gb‘agbelebu re si te le mi‖
ff Ona t‘O la l‘emi o rin
Ona t‘O la l‘emi o rin
Ona t‘O la l‘emi o rin
Em‘o tele, tele titi lae.

2 mf Em‘o ba koja ogba ni


Em‘o ba koja ogba ni
Em‘o ba koja ogba ni
Em‘o tele, tele titi lae.

3 mf Em‘o ba koja idajo


Em‘o ba koja idajo
Em‘o ba koja idajo
Emi o tele; tele titi lae.

4 ff Y‘o fun mi l‘ore at‘ogo


Y‘o fun mi l‘ore at‘ogo
Y‘o fun mi l‘ore at‘ogo
Y‘o je t‘emi t‘emi titi lae.
Amin.

719 Ongbe Olorun ngbe okan mi.


OD. 42:2.

1 mp Olorun mi ‘Wo l‘emi mi!


Ki imole oro t‘o la;
F‘agbara Re han l‘okan mi,
Ki O si mu mi l‘ara ya.
2 di Ongbe Re l‘o ngbe okan mi
N‘ile aginju gbigbe yi,
Ebi npa mi mo si daku,
cr ‘Fe Re nikan lo le yo mi.

3 IWO nikan l‘okan mi nfe,


N‘ile gbigbe yi, Olorun;
Mo fe ni ore-ofe Re
Ju gbogbo oro aye lo.

4 mf Ife Re t‘o sowon julo


Y‘o kun okan at‘ahon mi,
Ogo, ayo alafia mi
Y‘o je lati so iyin Re.

5 Gbogbo aye mi ni un o ma
F‘orin ope ‘bukun fun O;
Iyin t‘o ye oruko Re
Ni un o ma gbe s‘oke si O.

6 Oruko Re wa l‘enu mi
At' ero mi, lor‘ eni mi;
Mo n se asaro ise Re.
Pelu ‘wariri l‘oganjo.

7 Mo nri Owo Re n‘nu ‘se mi;


Nje un o korin titobi Re Olorun,
‘WO t‘O mu mi yo
Labe ojiji iye Re

8 f Mo sun mo O timotimo;
Agbara Re y‘o si gba mi
Low‘aye at‘ orun egbe
Igbala Re ki tase lae.
Amin.

720 8.7.8.7. & Ref.


Se alabapin pelu mi ninu iponju bi
omo-ogun rere Jesu Kristi.
II Tim. 2:3.

1 f E dide, omo igbala,


Eyin t‘e fe Oluwa,
Dide, ilu alagbara
Ki ota to de Sion.
ff F‘agbara re korin kikan,
Bi iro omi okun,
Nipa eje Kristi Jesu
Awa ju asegun lo
Awa ju asegun lo,
Awa ju asegun lo,
Nipa eje Kristi Jesu,
Awa ju asegun lo

2 cr Egbe mimo ti igbani


Ti won ti nrin ona yi;
mf W‘asia won t‘o nfe lele,
Asegun nipa Kristi.

3 f A ti gbe ‘ku mi ni ‘segun,


lye wa mbe n‘nu Kristi;
L‘OJO ‘farahan Oluwa
A o ho iho ayo.

4 f Laipe a o de‘biite Re.


Ao si mo Oba Ogo;
Nibe a oke, ―Kabiyesi‖.
Gbogbo wa y‘o gba ere.
Amin.

721 11.11.11.11. & Ref.


SO fun awon omo Israeli
ki won ki o tesiwaju Eks. 14:15.

mf E ma te siwaju, Kristian ologun,


Ma tejumo Jesu t‘O mbe niwaju,
Kristi Oluwa wa ni Balogun wa,
Wo! Asia Re wa niwaju ogun,
ff E ma te siwaju, Kristian ologun
Sa tejumo Jesu t‘O mbe niwaju

2 f Ni oruko Jesu, ogun esu sa,


Nje Kristian ologun ma nso si isegun
cr Orun apadi mi ni hiho iyin,
Ara, gb‘ohun yin ga, gb‘orin yin soke

3 f Bi egbe ogun nla n‘Ijo Olorun,


Di A ra, a n rin l‘ona t‘awon mimo nrin;
mf A ko ya wa ni ‘pa, egbe kan ni wa.
Okan ni ‘reti, ni eko ni ife

4 Ite at‘ijoba wonyi le parun,


1Sugbon Ijo Jesu y‘o wa titi lae,
cr Orun - apadi ko le bor‘ ijo yi,
A n‘ileri Kristi, eyi ko le ye.

5 f E ma ba mi kalo, eyin eniyan,


D‘ohun yin po mo wa, l‘orin isegun;
cr Ogo, iyin, Ola fun Kristi Oba!
Eyi ni y‘o maje orin wa titi.
Amin.

722 11.11.11.11. & Ref.


Iwo ti fi opagun fun awon ti o
beru Re. OD. 60:4.

1 f D idan l‘opagun wa, o ntoka s‘orun!


On f‘ona han ogun si ile t‘orun!
B‘a ti nlo l‘aginju, l‘a nf‘ayo gbadua
Pel‘okan isokan l‘a m‘on‘ orun pon.
Didan l‘opagun wa, O ntoka s‘orun,
O nf‘ona han ogun si ile t‘orun.

2 mf Jesu Oluwa wa, l‘ese mimo Re


Pelu okan ayo l‘Omo Re pade,
p A ti fi O sile, a si ti sako,
To wa Olugbala, si ona toro.

3 mf Jesu apere wa, ‘WO S‘Omode ri,


Se wa l‘omo rere, k‘a n‘iwa pele,
cr Li akoko ewu, nibo l‘a ba re?
B‘o ye li odo Re, Olugbala wa.

4 F TO wa l‘ojo gbogbo l‘ona t‘awan to,


Mu wa nso s‘isegun l‘ori ota wa;
di K‘angeli Re s‘asa wa ‘gb‘oj‘orun su
p Dariji, si gba wa l‘akoko iku.

5 f A ba le pe l‘awon angeli l‘oke


Lati jumo ma yin n‘ite ife Re:
cr ‘Gbat‘ ajo wa ba pin, isimi y‘o de;
ff At‘alafia, at‘orin ailopin.
Amin.

723 8.5.8.5. & Ref.


Sugbon eyi ti enyin ni, e di i mu
sinsin titi Emi o fi de. Ifi. 2:25.

1 f Ha! egbe mi e w‘a si a


Bi ti nfe lele!
Ogun Jesu fere de na,
A fere segun.
ff ―D‘odi mu, Emi fere de‖
Beni Jesu nwi,
Ran ‘dahun pada s‘orun, pe
―Awa o di mu.‖

2 f Wo opo ogun ti mbo wa;


Esu nko won bo;
Awon alagbara nsubu,
P A fe damu tan!

3 f Wo asia Jesu ti nfe,


Gbo ohun ipe;
A o segun gbogbo ota
Ni oruko Re

4 f Ogun ngbona girigiri,


Iranwo wa mbo;
Balogun wa mbo wa tete,
Egbe, tujuka!
Amin.

724 7.6.7.6.D.
Nitorina, e gbe gbogbo ihamora
Olorun WO. Efe. 6:13.

1 f Duro, duro fun Jesu,


Eyin Om‘ogun Krist‘
Gbe asia Re s‘oke
A ko gbodo fe ku;
Cr Lat‘ isegun de 'segun
Ni y‘o to ogun Re;
Tit‘ ao segun gbogb‘ ota
Ti Krist‘ y‘O j‘Oluwa.

2 f Duro, duro fun Jesu,


F‘eti s‘ohun ipe
Jade lo s‘oju ija
Loni ojo nla Re;
Eyin akin ti nja fun
Larin ainiye ota,
N‘nu ewu e ni ‘gboya,
E ko ‘ju ‘ja s‘ota

3 f Duro, duro fun Jesu,


Duro l‘agbara Re;
p Ipa eniyan ko to,
Ma gbekele tire,
cr Di ‘hamora ‘hinrere,
Ma s‘ona, ma gbadua,
B‘ise tab‘ ewu ba pe,
Ma se alaide ‘be.

4 f Duro, duro fun Jesu,


di Ija na ki y‘o pe;
p Oni, ariwo ogun,
f Ola, orin ‘segun!
ff Eni t‘o ba si segun!
Y‘o gba ade iye,
Y‘o ma ba Oba ogo
J‘oba titi laelae.
Amin.

725 S.M.
E je alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara
ipa Re. Efe. 6:10.

1 f Omogun Krist‘ dide,


Mu ‘hamora yin wo;
Lo ipa t‘Olorun fun yin,
Nipase Omo Re.

2 cr Gbe ‘pa Olorun wo,


T‘Oluwa om‘ ogun,
Eni t‘o gbekele Jesu,
O ju asegun LO

3 mf Ninu ipa Re nla,


O ni ki E duro,
Tori k‘e ba le jija na,
E di ‘hamora yin.

4 CR LO lat‘ ipa de ‘pa


Ma ja, ma gbadura;
Te agbara okunkun ba,
E ja, k‘e si segun.

5 Leyin ohun gbogbo,


Leyin gbogbo ija,
K‘e le segun n‘ipa Kristi
K‘e si duro sinsin.
Amin.

726 C.M.
Awon ogun orun si nto O lehin.
Ifi. 19:14.

1 f Omo Olorun nip s‘ogun,


L‘ati gb‘ade Oba;
Opagun Re si nfe lele.
Ta lo ‘s‘om‘ ogun Re?

2 mp Eni t‘o le mu ago na,


T‘o le bori ‘rora,
cr T‘o le gbe agbelebu Re,
f On ni om‘ ogun Re

3 mf Ajeriku ti o ko ku,
T‘o r‘orun si sile;
T‘o ri Oluwa Re loke,
T‘o pe k‘O gba On la.

4 di Pelu idariji l‘enu


Ninu ‘rora iku,
cr O bebe f‘awon t‘o np‘a lo,
f Tani le se bi Re?

5 ff Egbe mimo; awon wonni;


T‘Emi Mimo ba le,
Awon akoni mejila;
Ti ko ka iku si.

6 f Won f‘aya ran ida ota,


Won ba eranko ja,
di Won f‘orun won lele fun‘ku
Tani le se bi won?

7 ff Egbe ogun t‘agba t‘ewe,


L‘okunrin l‘obinrin
Won y‘ite Olugbala ka.
Won wo aso funfun.

8 f Won de oke orun giga,


di N‘nu ewu on 'ponju:
p Olorun fun wa l‘agbara
Ki a le se bi won.
Amin.

727 C.M.
Ma aja ija rere ti igbagbo.
1 Tim. 6:12.

1 mf Ajagun Jesu J‘emi bi?


At‘omo ehin Re?
Un o ha beru lati wasu
Agbara isin Re?

2 mf Ao ha gbe mi soke orun


Lori busun rorun,
‘Gbati opo ja f‘ere na
Lori okun eje

3 Ko ha s‘ota lati ba ja?


Un o ha ko ‘gbi lile?
Aye ha fe ore-ofe
T‘y‘ o mu mi d‘odo Re?

4 Mo ni ja, bi un o ba joba,
P Ran ‘gboya mi lowo!
Un o f‘ara da gbogbo ise
Pelu iranwo Re
Amin.

728 S.M.
E ma sona ki e si ma gbadura,
ki e ma ba bo sinu idewo. Mk. 14:38

1 mf Ma SO ‘ra, okan mi,


Awon ota dide;
di Ogun ese si mura tan
Lati fa O lu ‘le.

2 mf Maja‘ ma gbadura,
Mase so ‘reti nu;
Bere l‘otun l‘ojoiumo.
Tor‘ agbara loke.

3 mf Ma ro p‘o ti segun,
Ma si se tu ‘ra ‘le;
Ise re ki o pin titi
IWO o fi gb‘ade.

4 mf Ma ja lo okan mi,
Tit‘ iku y‘o fi de;
Olorun y'o mu o lo 'le,
‘Gb‘emi re ba pinya.
Amin

729 9.6.9.6. Ref.


Sugbon, awon ti o ba duro, de Oluwa
yio tun agbara won se. Isa. 40:31

1 mf Eyin olukore nin'oko


T‘are fere mu tan
cr E roju duro de Oluwa,
Y'o s‘agbara d'otun.
Awon t‘o duro d‘Oluwa,
Y‘o s‘agbara won d‘otun,
f Won o fi iye fo,
Won o fi iye fo bi idi,
Won o sa, won ki y‘o kare
Won o rin, ki y‘o re won
Won o sa, won ki y‘o kare
Won o rin, ki y‘o re won
Won o sa, won ki y‘o kare
Y‘o rin, k‘y‘o re won.

2 p Nigba are ati ‘rewesi,


A ngb‘okan wa si O;
mf Leyin t‘a gba Olugbala gbo,
Ki l‘ao tun beru.

3 f E yo! O mba wa gbe l‘ojojo


Ani titi d‘opin;
Woke! esi ma tesiwaju.
Y‘o fun nyin l‘agbara.
Amin

730 .
Tre li emi, gba mi. OD. 119:94.

1 mf Tire titi lae l‘awa se


Ouwa wa orun!
cr K'ohun at‘okan wa wipe;
Amin, beni k‘o ri.

2 mp ‘Gbati aye ba ndun mo ni,


T‘o si nfa okan wa;
p K‘iro yi pe: ―Tire l‘awa‖
Le ma dun l‘eti wa.

3 mp ‘Gba t'ese pelu etan re


Ba fe se wa n‘ibi;
p K‘iro yi pe, ―Tire l‘awa‖
Tu etan ese ka.

4 mf ‘Gbati esu ba ntafa re


S‘ori ailera wa;
f K‘iro yi pe: ―Tire l'awa‖
Ma je ki o re wa.

5 mf Tire, n‘igb‘a wa l‘omode


cr Tire, n‘igb‘ a ndagba
di Tire, n‘igb‘a ba ndarugbo
p Ti aye wa mbuse.

6 ff Tire, titi lae l‘awa se;


A f‘ara wa fun O;
Titi aye ainipekun,
Amin, beni k‘o ri.
Amin.

731 C.M.
Emi nlepa lati de opin ire-ije ni fun
ere ipe giga Olorun. Fili. 3:14.

1 f Ji, okan mi dide giri,


Ma lepa nso kikan;
F‘itara sure ije yi,
P Fun ade ti ki sa.

2 mf Awosanma t‘o yi wa ka,


Ni eleri ‘se re;
Gbagbe irin at‘eyin wa,
Sa ma tesiwaju.

3 f Olorun nfohun isoji


Ke si o lat‘ oke;
Tika Re l‘O npin ere na,
F‘oju t‘o ns‘aferi.

4 mf Olugbala, ‘Wo l‘o mu mi


Bere ‘re ‘je mi yi;
Nigbat‘ a ba de mi l‘ade,
Un o wole l‘ese Re.
Amin.

732 8.7.8.7.D.
Sugbon ohunkohun ti o jasi ere fun
mi, awon ni mo ti kasi ofo nitori
Kristi Fili. 3:7.

1 Jesu, mo gb‘agbelebu mi
Ki nle ma to O leyin;
Otosi at‘eni egan,
‘WO l‘ohun gbogbo fun mi
Bi ini mi gbogbo segbe
Ti ero mi gbogbo pin
Sibe, oloro ni mo je!
T‘emi ni Krist‘ at‘orun.

2 Eda le ma wahala mi,


Y‘o mu mi sunmo O ni;
Idanwo aye le ba mi,
Orun o mu ‘simi wa,
Ibanuje ko le se nkan
Bi ‘fe Re ba wa fun mi;
Ayo ko si le dun mo mi
B‘iwo ko si ninu re

3 Okan mi, gba igbala re;


Bori ese at‘eru;
F‘ayo wa ni ipokipo,
Ma sise lo, ma weyin,
Ro t‘emi t‘o wa ninu Re
At‘ ife Baba si o!
W‘Olugbala t‘O ku fun o
Omo orun mase kun.
4 Nje koja lat‘ore s‘ogo
N‘nu adura on ‘gbagbo;
Ojo ailopin wa fun O,
Baba y‘o mu o de ‘be,
Ise re l‘aye fere pin
Ojo ajo re nbuse,
Ireti y‘o pada ‘sayo,
Adura s‘orin iyin.
Amin.

733 10.9.10.9. & Ref.


E fi ayo sin Oluwa. OD. 100:2.

1 f Pelu ayo l‘ao sise f‘Oluwa,


Pelu ife l‘ao f‘OWO wa se
Isekise ti o ba yan fun wa!
L‘ododo l‘ao sise ‘ranse wa,
cr Sise fun Jesu.
L‘ayo l‘a o lo l‘ayo l‘ao lo;
Sise fun Jesu,
Ninu ogba Re laye.

2 f Pelu adun li ao so itan na;


T‘ife nla re s‘awa eniyan,
Kristi itansan ogo ti Baba,
L‘ofe l‘On ofi ‘bukun fun wa.

3 p Pelu‘rele l‘ao sise f‘Oluwa


Ao fi otito rin l‘ona Re;
Ao'to asako s‘od‘ Olugbala,
Ao f‘Odagutan han elese
Amin,

734 8.7.8.7. & Ref.


Omo, lo loni ninu ogba ajara mi.
Mat. 21:28.

1 mf Gbo bi Oluwa ti mbebe,


Ise wa fun gbogbo wa;
cr Gbo bi Emi ti nwi pelu,
Je ipe na bayi pe:
f ―Mo setan lati sise fun O Jesu,
Emi de, ran mi;
cr Mo nfe lati se ife Re ni pipe,
Un o lo s‘ibit‘O ba ran mi
f Mo setan lati sise fun O Jesu
Emi de, ran mi;
Bi ona tile sokun, eru ko bami
Mo se tan fun ise Jesu.
2 cr Ohun kan npe o nisiyi,
Fi eti si ohun na;
mp O n so si o l‘eti jeje,
Je ipe na bayi pe.

3 di Okan pupo nku n‘nu ese,


Yara lati se ‘ran wo;
‘Tori akoko nkoja lo,
So fun Jesu bayi pe.
Amin.

735 1.1.1.1.
Ki enyin kofi ara nyin fun Olorun li
ebo aaye mimo, itewogba. Rom. 12:1.

1 mf Gba aye mi, Oluwa,


Mo ya si mimo fun O,
Gba gbogbo akoko mi,
Ki won kun fun iyin Re.

2 f Gba OWO mi, k‘o si je


Ki nma lo fun ife Re,
Gba ese mi k'o si je
Ki won ma sare fun O.

3 Gba ohun mi, je ki nma


Korin f‘Oba mi titi;
Gbe ete mi, je ki won
Ma Jise fun O titi.

4 mf Gba wura, fadaka mi,


Okan nki o da duro;
Gba ogbon mi ko si lo
Gege bi O ba ti fe

5 mp Gba ‘fe mi fi se Tire,


Ki o tun je t‘emi mo;
Gb‘okan mi, Tire n‘ise,
cr Ma gunwa nibe titi.

6 f Gba ‘feran mi Oluwa,


Mo fi gbogbo re fun O;
Gb‘emi papa, lat‘ oni
Ki ‘m‘je Tire titi lae.
Amin.

736 7.6.7.3.7.7.7.3
Emi ngbagbe aopn nkan ti o wa lehin,
mo si n noga wo awon nkan ti o wa niwaju.
Fili. 3:13.
1 f Gbekele Olorun re
p K‘o ma nso! K‘o ma nso!
D‘ileri Re mu sinsin,
K‘oma nso!
Mase se oruko Re,
B‘o tile mu egan wa,
Ma tan ihin Re kale,
Si ma nso.

2 f O ti pe o s‘ise Re?
cr Sa ma nso! Sa ma nso!
p Oru mbo wa,'mura sin!
Sa ma nso!
Sin n‘ife at‘igbagbo;
f Gbekele agbara Re,
Fi ori ti de opin,
Sa ma nso.

3 f O ti fun o ni ‘rugbin?
Sa ma nso! Sa ma nso!
Ma gbin ‘wo o tun kore,
Sa ma nso;
Ma sora, si ma reti
L‘enu ona Oluwa;
Y‘o dahun adura re,
Sa ma n so!

4 p O ti wipe opin mbo?


cr Sa ma nso! Sa ma nso!
Nje fi eru mimo sin!
Sa ma n so!
Kristi l‘atilehin re,
On na si ni ounje re,
Y‘o sin o de 'nu ogo,
Sa ma nso.

5 f Ni akoko die yi;


Sa ma nso! Sa ma nso!
Jewo Re ni ona re
Sa ma nso!
K‘a ri okan Re n‘nu re,
K‘ife Re je ayo re,
L‘ojo aye re gbogbo
Si ma n so!
Amin.

737 7.6.7.5.D. or 13.12.13.12.


Oru mbo wa nigbati enikan ki yo le sise.
Jn. 9:4.
1 f Sise ‘tori oru mbo! sise li owuro;
Sise nigbat‘ iri nse; sise n‘nu tanna;
Sise ki osan t‘o pon, sise nigb‘orun n
ran;
Sise ‘tori oru mbo! gba ‘se o pari.

2 f Sise ‘tori oru mbo! sise l‘osan gangan;


F‘akoko rere fun ‘se, isimi daju;
F‘olukuluku igba ni nkan lati pamo;
Sise ‘tori oru mbo! ‘gba se o pari

3 f Sise‘tori oru mbo! Sise l‘oju ale,


Sise ‘gbat‘ imole wa, ojo bu lo tan;
Sise titi de opin, sise titi d‘ale,
p Sise ‘gbat‘ ile ba nsu, ‘gba‘se o pari.
Amin.

738 12.12.12. & Ref.


Awa o duro sinsin ninu iranse na. .
Ise A. 6:4.

1 f A o sise! Ao jise! Om‘olorun ni wa,


Je k‘a tele ipa ti Oluwa wa to;
mp K‘a fi 'moran Re SO agbara wa dotun,
cr K‘a li gbogbo okun wa sise t‘a ose.
f Foriti! Foriti!
Ma reti: ma sona,
Titi Oluwa o fi de.

2 mf A o ise! Ao sise! bo awon t‘ebi npa,


Ko awon alare lo s‘orisun iye;
Ninu agbelebu l‘awa o ma sogo,
‘Gbati a ba nkede pe: ―Ofe n‘igbala‘‘

3 f A o sise! ao sise gbogbo wa ni y‘o se,


Ijoba okunkun at‘isina y‘o fo;
A o si gbe oruko Jehofa l‘eke,
N‘nu orin iyin wa pe; ―Ofe n‘igbala‘‘

4 f A o sise! ao sise! lagbara Oluwa,


Agbada at‘ ade y‘o si je ere wa;
‘Gbat‘ ile awon oloto badi tiwa,
ff Gbogbo wa ojo ho pe: ―Ofe n‘igbala.
Amin.

739 4.10.10.10.4.
LO sise loni ninu ogba ajara mi.
Mat. 21:28.
1 Wa, ma sise,
f Tani gbodo s‘ole ninu oko
‘Gbati gbogbo eniyan nkore jo,
Kaluku ni Baba pe fun ise;
―Sise loni.‖

2 Wa, ma sise,
Gba ‘pe giga ti angeli ko ni
Mu ‘hinrere to t‘agba t‘ewe lo,
di Ra ‘gba pada, wawa l‘akoko nlo,
Ile su tan.

3 mf Wa, ma sise,
Oko po, alagbase ko si to,
cr Aye titun po fun wa lati kun,
Ohun ona jinjin, at‘itosi
Nkigbe pe; ― Wa‖

4 f Wa, ma sise
Le ‘yemeji on aigbagbo jina,
K‘o s‘alailera ti ko le se nkan,
di Ailera f‘Olorun a ma lo ju '
Fun‘se nla Re

5 cr Wa, ma sise,
‘Simi ko si nigbat‘ ise osan,
Titi orun yio fi WO l‘ale,
f Ti awa o si gbo ohun ni pe:
―O seun, omo‖

6 Wa, ma sise,
Lala na dun ere re si daju,
cr ‘Bukun f‘awon t‘o fori ti d‘opin
Ayo won, ‘simi won y‘o ti po to!
p ―Lo d‘ Oluwa‖.
Amin.

740 C.M.
A npawada si aworan kanna, lati ogo de
ogo. II Kor. 3:18.

1 mf Jesu mase je k‘a simi


Tit‘ O fi d‘okan wa;
T‘O fun wa ni ‘bale aya,
T‘O wo ite ese

2 p A ba le wo agbelebu,
Titi iran nla na
Y‘o so ohun aye d‘ofo,
T‘y'o mu ‘banuje tan.
3 cr Titi okan wa yo goke,
T‘ao bo lowo ara;
T‘ao fi r‘alafia pipe,
Ati ayo orun.

4 f Bi a si ti ntejumo O,
K‘a d‘okan pelu Re;
K‘a si ri pipe ewa Re
N‘ile ayo l‘oke.
Amin

741 L.M.
E fi ayo sin Oluwa.
OD. 100:2

1 mf Ki l‘awa y‘o fun Olorun


Fun gbogbo ore Re si wa?
f A o f‘ayo ranti Oko Re,
A o si fi iyin Re han.

2 mf IWO li olu ife wa,


L‘odo Re l‘a nr‘ohun gbogbo
Si orisun lat‘oke wa,
Je k‘o san si okan gbogbo.

3 Be l‘ao kede agbara Re,


At‘ or‘-ofe Re f‘elese;
Titi gbogb‘ eda y‘o mo O
Ti won o si tewo si O.

4 mp Silekun sile fun ‗se Re,


T‘aye at‘esu ki o le si,
Je k‘oro Re ma gbe ‘nu wa
Ki eso na k‘o wa titi.

5 ‘Bukun eso afunrugbin,


K‘a le ma so eso titi;
K‘a tan ‘hinrere Re k‘aye
Ati otito Re titi.

6 mf A o mo titobi ipa Re,


‘Gba t‘a ba se wa pe n‘ife;
Bi owon n‘ile Olorun.
L‘ao duro, t‘ao ni jade mo
Amin.

742 8.8.6.D.
E ma ni igbona okan, e ma sin Oluwa.
Rom. 12:11.
1 mf Jesu inu wa ti dun to,
Pe, a je omo eyin Re;
Awa t‘a nf‘aye wa
Gbo t‘Olorun ati t‘eda,
A n f‘osan se ise rere
A n f‘oru gbadura.

2 cr A ko r‘aye fun iroju,


Tabi fun imele sise;
Awa nte siwaju;
Are ara ko si rara,
F‘eni ti o nsin Olorun
T‘o mo Iwo nikan.

3 mf T‘ojo, t‘erun l‘o nyara lo,


Akoko na ko to fun wa
Lati korin ‘yin Re,
Wakati ayo na ko to,
A fedapo m‘ogun orun
Korin ayeraye.

4 mf Awa nfe lati ma yin O,


cr Pelu awon ogun orun;
f Awon egbe didan
di Ti nke Mimo, Mimo, Mimo!
f K‘a ma korin y‘ite Re ka,
ff Orin ayeraye.
Amin.

743 8.8.8.D.
Ni ise sise e ma se ole.
Rom. 12:11.

1 mf Awon ti nfise won f‘ale,


Won nfi t‘Oluwa jafara;
Awon ti nfisin se ‘boju
Ko mo ise on igbagbo;
Won ya‘hun t‘Olorun so PO
Aapon ati ifokansin.

2 mf A f‘idi ise wa mule,


T‘a nse pelu ‘tara emi;
Olorun to da gbogb‘ ojo,
Ni k‘a simi l‘OJO keje;
Ba ti nfise ra ‘gba pada
Dun mo Oluwa ti a nsin.

3 A o ma yo, bi Olorun
Fun wa n‘ise on itara;
cr N‘tor‘ ise ti on f‘ase si
f Y‘o di ebo fun ogo Re,
B‘awon eni mimo l‘oke
B‘a ti njosin n‘ife npo si.
Amin.

744 8.6.8.6.8.6.
Baba mi nsise titi di isisiyi, emi si nsise
Jn. 5:17.

1 mp Jesu ma yo mi n‘nu‘se Re.


TO mi fun ife Re;
N‘tor‘ emi ko le sa iri se
L‘oko tito bi yi;
Emi ko ni bere oya
Ki nsa ma sin O si.

2 mf Opo li awon ti nsin O,


Aye wa f‘opo si;
Ise itoju ajara
L‘O yan f‘awon miran;
Awon akoni mbe l‘ogun
Omode mbe n‘ile.

3 Gbogbo ise li o dara,


B‘o ba sa ti wu O;
Bi osise nfife josin,
Ise re y‘o wu O;
‘WO ki o sai bukun ise
At‘osise pelu

4 Jesu ti se iru ise;


T‘On ni k‘a se loni,
Eni ba ni‘pin n‘nu'se Re;
Y‘o ba jogun pelu;
Un o sise ki nle j‘omo Re;
di Jowo mase yo mi.
Amin.

745 8.7.8.7.D.
E ya Barnaba on Saulu soto fun mi fun ife
ti mo ti pe won si. Ise A. 13:2.

1 mf Gbo ohun Jesu ti nke pe;


―Tani y‘o sise loni;
Oko pon pupo fun ‘kore;
Tani y‘o lo ko wa ‘le?‖
cr Kikankikan l‘Oluwa npe,
Ebun nla ni y‘O fun o,
Tani y‘o fi ayo dahun
f Pe: ―Emi ni yi; ran mi?

2 mf B‘iwo ko le la okun lo
Lati w‘awon keferi;
O le ri won nitosi re,
Nwon wa l‘enu ona re;
B‘o ko le fi wura tore,
Ebun miran ko kere,
Die t‘o si se fun Jesu,
‘Yebiye ni l‘oju Re.'

3 mp B‘iwo ko le se alore
L‘ori odi Sioni
Lati t‘oka s‘ona orun;
p Lati fiye lo eda;
‘Wo le f‘adura at‘ore
Se ohun t‘Olorun wi;
cr 'Wo le se gege bi Aaron!
T‘o gb‘owo woli soke.

4 mf Ma je k‘a gbo ki o wipe,


Ko si nkan t‘emi le se!
Nigbat‘ emi eniyan nku
Ti Oluwa si npe O,
F‘ayo gba ise t‘O ran o,
F‘ise Re se ayo re;
ff ‘Gba t‘o npe o, tara dahun
Pe: emi ni yi; ran mi!
Amin

746 8.7.8.7. & Ref.


Wo o, awa ti fi gbogbo re sile awa si
nto O lehin. Mat. 19:27.

1 mf Mo fi gbogbo re fun Jesu


Patapata, laiku ‘kan;
Un o ma fe, un o si gbekele,
Un o wa l‘odo Re titi.
f Mo fi gbogbo re,
Mo fi gbogbo re,
Fun O, Olugbala mi, ni
Mo fi won sile.

2 Mo fi gbogbo re fun Jesu,


mp Mo fi ‘rele wole fun;
Mo fi ‘gbadun aye sile,
cr Gba mi, Jesu, si gba mi.

3 Mo fi gbogbo re fun Jesu,


Se mi ni Tire nikan;
cr Je ki nkun fun Emi Mimo,
Ki n mo pe, ‘Wo je t‘emi.

4 Mo fi gbogbo re fun Jesu,


Mo fi ara mi fun O;
Fi ‘fe at‘agbara kun mi,
Ki ‘bukun Re ba le mi.

5 Mo fi gbogbo re fun Jesu,


Mo mo p‘Emi ba le mi;
f A! ayo igbala kikun;
Ogo, ogo, f‘oko Re.
Amin

747 L.M.
E ma ronu awon nkan ti mbe loke, ki i se
awon nkan ti mbe li aiye: Kol. 3:2.

1 mf Olugbala, jo sokale!
F‘or‘-ofe Re ran mi l‘owo;
Yo ife aye l‘okan mi.
Pese aye fun ara Re.

2 Fi ara Re kun emi mi


Ki O si so mi d‘ominira!
‘Ko fe le ‘pa ohun miran
Bikose ‘WO losan l‘oru.

3 Niwon ‘gbati mo wa l‘aye


Nki 'o'lepa ire miran;
Emi y‘o dagbere f‘aye,
Pelu gbogbo itanje re.

4 Ona t‘Olugbala mi rin,


Ni uno f‘iyara wa kiri;
Beeli emi ki o si mo
Ife miran leyin Tire.

5 f Lat‘oni lo, k‘adun aye


Ma ri ibi gba l‘okan mi;
Se ni Tire, eto Re ni,
IWO n‘ise Oluwa re.

6 Oro, ola afe asan


Ti aye yi le fifun ni;
Okan mi ko gbogb‘ etan yin
Kristi nikan ni y‘o ma sin.

7 F IWO nikan ni mo le fe;


Pelu ife atinuwa;
Ayo wol‘otobi toyi
Pe, IWO gba mi ni Tire!

8 Ko s‘ohun ti mo fe l‘aye
Ju k‘ife Re wa l‘aya mi;
Eyiyi sa ni mo ntoro,
Mo ko ohun gbogbo ‘yoku.
Amin.

748 L.M.
Nje nisisiyi, Oluwa, kini moduro de?
Ireti mi mbe li Odo Re OD. 39:7.

1 mf Kili ohun ti mo nlepa?


Kini ‘reti at‘ife mi?
Ki ntele odagutan na,
Ki nma lepa aworan Re.

2 Gbogbo ‘reti mi mbe n‘nu Re,


Pe ki ntun je eni t‘O fe;
cr Ki nri igbala Re laye,
Ki nsi je adun Re l‘oke.

3 di Mo npongbe f‘Oluwa iye


mp Ti o ku l‘oke Kalfari;
F‘orisun omi, on eje
Ti nti ‘ha Imanuel jade.

4 cr Mo npongbe f‘omi ife Re:


Emi ayo ti a ko mo,
Ki emi si tun mu l‘oke
p B‘o ti nsun l‘at‘ ori ite.
Amin.

749 7.6.7.6.D.
Ki eyin ki o fi ara nyin fun Olorun li
ebo aaye Rom. 12:1.

1 mf Emi, okan at‘ara;


Jesu mo fi fun O;
Fun ebo mimo lati
Ma je Tire titi,
cr Mo fi ara mi rubo,
Jesu Tire l‘emi,
Ki ‘gbagbo mi mase ye
di Se mi n‘tire nikan.

2 mf Jesu, Olugbala nla,


Mo gbeke mi le O;
Mo wa igbala nla Re,
Mo bere ‘leri Re;
di Mo gba aya ara mi
Kuro labe ese;
Mo fi fun b‘ohun elo
Lati lo si segun.

3 mp Mo f‘ise t‘ara sile


Ki nle wa l‘odo RE,
Jesu Olugbala mi,
mf F‘emi Re sinu mi;
Tire li emi, Jesu,
T‘a f‘eje Re we mo
T‘Emi ti ya si mimo,
Ebo fun Olorun.
Amin.

750 6.5.6.5.D. & Ref.


Nigbana li emi wipe, Emi niyi:
ran mi. Isa. 6:8.

1 mp Gbe ewa Re wo mi
Bi mo ti njosin,
cr Mo jewo ara mi
Fun O Oluwa;
Fi ewu ogo Re
Se oso fun mi;
mf Ki nle di asegun
Ni gbogb‘ aye mi,
Emi pelu Jesu,
Idapo didun;
cr Okan ti Jesu njoba
L‘od‘ omnira.

2 mp Fun mi ni iran na
Ti o ngoke lo
Si ibi ite Re,
Ki nye s‘aniyan,
mf Ohun gbogbo y‘o si
Sise fun ire;
Gbogb‘ ohun t‘o diju
Y‘o ye mi gbangba.

3 cr Nibi agbelebu
Jo, fa mi mora,
Ki nmo agbara Re;
F‘ese mi mule,
Wa, we mi mo laulau,
M‘abawon kuro;
Ese nso mi d‘eru,
So mi d‘omnira.
4 p Fun mi l‘okan mimo
At‘inu funfun;
Ki nsa le ma segun
Ni gbogb‘aye mi;
B‘ogun tile gbona
T‘ija na si le,
f Pelu Re, Asegun,
Isegun daju.
Amin.

751 L.M.
Oun yoo fi Emi Mimo ati ina baptist nyin.
Lk. 3:16.

1 IWO t‘o t‘oke sokale


Lati f‘ina orun fun ni,
cr Da ina ti ife mimo
Li ori pepe aya mi!

2 Je k‘o jo f‘ogo Re nibe


Pelu oWO ina aiku;
mf K‘o ba ebo ati iyin.
Pada goke si odo Re

3 cr Jesu, mu fe okan mi se
N‘ise, l‘oro, l‘ero fun O;
Ki nma so ina mimo na,
Ji ebun Re dide n‘nu mi;

4 Kin mura lati se ‘fe Re,


Ki ntun se ise ‘gbagbo mi,
di Tit‘ iku y‘o f‘anu Re han
T‘ebo na y‘o si di pipe.
Amin.

752 S.M.
Busi igbagbo wa. Lk. 17:5.

1 mf Jenu, emi fe ri
Itura Re n‘nu mi,
Ajo anu Re f‘araye,
Ife gbigbona Re

2 cr K‘Emi Re gbe ‘nu mi;


K‘inu Re yo si mi;
Beni ‘gbona itara mi
Y‘o je ife mimo.
Amin.
753 C.M.
Tani yoo ha ya wa kuro n 'nu ife Kristi?
Rom. 8:35.

1 mf Jeki Eni ti o ni wa,


Joba li okan wa,
K‘O si gba orin opo wa
Ati gbogbo ‘fe wa.

2 Awa je Tire nitoto,


Eni ra wa pada;
cr Toku-taye onigbagbo
Ti Kristi nikan ni.

3 cr Jesu, jowo gb‘awon Tire,


Mu ‘fe okan wa se.
Jeki a wa fun ogo Re,
K‘a ku s‘enu ‘se Re

4 Tokan-tara wa l‘a fun O,


Gbogb‘ ohun ti a ni
f L‘a fi fun O, tayo-tayo,
Titi ayeraye.
Amin.

754 8.8.8. D.
Ni igbona okan, e ma sin Oluwa.
Rom. 12:11.

1 mp Oluwa, wo iranse Re!


Mas‘ aifi oju Re to mi,
cr Ki ngbo, ki npa Oro Re mo,
Ki nwadi, ki nsi se ‘fe Re,
Ki nma se gbekele ‘se mi,
Sugbon ki nmu ododo se

2 mp B‘ or‘-ofe Re ba je lo mi,
Emi eni ainilari,
cr Yan ‘se on akoko fun mi,
Jeki nso eso ninu Re;
Jeki ns‘ise mi pelu Re,
Si ba mi se li asepe.

3 p Ailera ni gbogb‘ ero mi,


Se b‘o ti ye li oju Re;
cr Jesu, ki‘se mi je Tire!
Oluwa, pipe n‘ise Re.
O si to loju Baba Re;
Rere ni gbogbo ise Re
4 cr Mo fara mi le O lowo;
Se mi b‘o ti to loju Re!
Fi ami Re si ara mi,
Si jeki nmu Oro Re se.
mf Ki nsin O pelu okan kan,
Ki nwa, ki nku fun ogo Re
Amin.

755 11.11.11.11. & Ref.


Emi wa ki won le ni iye, ani ki won le
ni lopolopo. Jn. 10:10.

1 cr O ha ngbekele Jesu n‘gbogb‘ona re?


O ha nd‘otun lokan re lojojumo?
O ha j‘om‘eyin Re? ye oro Re wo.
Y‘o fun o l‘Emi Mimo lopolopo
mf Lopolopo si, lopolopo si,
Ki won le ni iye si lopolopo
Lopolopo si, lopolopo si,
Ki won le ni iye si lopolopo,

2 mf Fun oju rere Re, gbe oko Re ga,


Olugbala wa to t‘orun sokale,
K‘awon ayanfe Re juba oro Re.
Eni ra wa pada nipa eje Re

3 cr Wa pelu igbagbo, wa je ipe Re


Eyin t‘a mbukun, jowo ara yin fun;
Jesu, y‘o gb‘eni t‘o sa wa sodo Re,
Y‘O da ‘bukun Re lu o lopolopo.
Amin.

756 8.7.8.7. & Ref.


Awon eni irapada Oluwa yio wa si
Sioni ti awon ti orin; ikanu ati ofo yio fo
lo Isa. 51:11.

1 f K orin t‘ife ‘yanu Jesu,


Anu at‘ or‘-ofe Re;
Yio pese ayo fun wa
N‘ile Baba Re loke.
‘Gba ta ba d‘orun rere,
Bawo li ayo wa yo ti po to!
Gba ta ba ri Jesu,
Ao yo, ao korin isegun.

2 mp B‘a ti nrin lo l‘on‘ajo wa,


Okun yo su l‘ona wa,
f Laipe oru ekun yo di
Owuro orin ayo
3 cr E je ka ma foriti lo,
Ka ma sin tokantokan;
f Taba ri ninu ogo Re,
Ao gbagbe iponju wa.

4 f Tesiwaju, ere daju;


Laipe ao ri ewa Re;
Ao silekun ita wura
N‘biti ao'ma gbe titi.
Amin.

757 11.11.11.11.
Eniti eyin fe lairi.
I Pet. 1:8.

1 cr Jesu, mo fe O, mo mo p‘O je temi,


Mo f‘aye ese sile nitori Re;
mf Iwo l‘Olugbala, Olurapada;
Bi nko fe O tele n‘siyi mo fe O.

2 cr Mo fe O n‘tori ‘Wo lo koko fe mi,


O ra ‘dariji fun mi ni Kalfari
mp Mo fe O ‘Wo lo d‘ade egun fun mi:
Bi nko fe O tele, n‘siyi mo fe O.

3 mf Ni iye tabi ni kiku un o fe o,


Un o fi gbogbo ojo aye mi yin O;
cr Nigba iku un o si ko orin yi pe:
Bi nko fe O tele, n‘siyi mo fe O

4 mf Ninu ogo didan ti ainipekun,


IWO lemi o ma f‘iyin fun titi;
f Un o korin pel‘ade ogo l‘ori mi,
Bi nko fe O tele, n‘siyi mo fe O.
Amin.

758 14.9.14.9. & Ref.


A fi ipile re sole lori apata.
Mat. 7:25.

1 mf A n kole l‘or‘apata t‘ijikiji ko le mi,


‘Pile wa daju, o lagbara;
Ise wa nihin ni lati segun gbogbo ibi,
K‘a si gbekel‘Orisun ‘ranwo
cr Apata
(A nkole l‘or‘Apata,)
Apata,
(L‘or‘Apata to daju,)
Apata ayeraye to duro lae (duro lae)
Apata
(A nkole l‘or‘ Apata,)
Apata
(Apata to ni ‘bukun)
f A nkole l‘or‘Apata, Kristi Jesu.

2 cr Ko si ‘pile ta le fi sole lon‘aiinokan wa


To le duro b‘igbi ‘ponju do;
f Sugbon lori Krist‘ Apata l‘abo to daraju,
Nitori ike Re l‘o daju.

3 mf Je ka sise, ka ko‘rin ninu tempil'mimo


yi.
Ninu ‘sin Re ao ri ‘bukun gba;
Taba f‘ayo ati ‘sowopo sise f‘Oluwa
Ere wa ni ayo ailopin
Amin

759 7.7.7.7D
Omo, lo loni ninu ogba ajara mi.
Mat. 21:28.

1 mf Gbo b‘Olugbala ti wi
Pe ise po n'nu ogba;
Alagbase ko si to
cr O mura ‗se na bi
Afunrugbin funrugbin,
Oko pon, ikore de,
Olukore mu doje
Lati ko 'rugbin wale.

2 f Olugbala nke tantan


P‘eyin onise dide,
Gbe Ihamora mi wo,
Mura fun 'se lat‘ oni
Akoko mure tete,
Ojo Ikoro de tan,
Olukore ti se tan,
Lati ko iti wole.

3 mf Wundia mewa la yan,


di Marun ko mura sile;
Marun to ti mura tan
Ba Oba Ogo wole.
cr Lo talent ta fi fun o,
Sse ‘ranse re loni
Fori ti, tesiwaju,
'Wo o gbade isegun.

4 f Gbo ipe Olugbala,


Wa je ‘pe na nisiyi,
Mase f‘akoko dola,
Ojo igbala de tan.
cr Ohun to npe nisiyi
Le dekun ipe lola,
Se ‘pinnu rere loni
Ko le gba ade ogo.

5 mf Oluwa, Olorun mi,


Un O fi ayo jise Re;
cr Fun mi ni ebun ahon,
Ki njise na laiberu;
Nigbayi li okan mi
Y‘o ma korin iyin pe:
f Ti Oluwa Olorun
Ni iyin ati ogo.
Amin.

760 8.7.8.7.D. & Ref.


Enu bode mejeji lajo pearli mejila
Ifi. 21:21.

1 M o fi won sile fun Jesu


Aye asan ko je nkan:
cr Gbogbo adun re bi egbin,
Gba mba ranti Kalfari;
B‘ore tile ko mi sile,
Ti o ku emi nikan;
mf Mo l‘ore kan to wa n‘tosi
Nigba ‘lekun pearl ba si
mp Aye yi yo rekoja,
Orun re yoo si wo;
f Nko ni mo ‘banuje mo
Nigba ‘lekun pearl ba si.

2 mf ‘Gba mo gbohun Jesu to npe,


At‘ipejeje angel,
Un o ro mo Olugbala mi
La afonifoji ja;
Un o d‘ileri Re owon mu
To ju oro ayejo,
f ―Maberu, un o wa pelu re
Nigba ‘lekun pearl ba si‖.

3 mf Ni ikoja odo Jordan,


At‘afefe tutu Re:
N‘igi iye, aiku ngbile
Ti omi iye si nsan;
N‘ile ayo awon mimo
N‘isura ainiye wa,
Awon angeli si nduro
Nibi ‘lekun pearl si‘le.
Amin.

761 L.M. & Ref.


O fiwaju won, awon agutan si nto
lehin Jn. 10:4.

1 mp O na t‘O yan l‘emi o to,


‘Tori mo gbeke mi le E,
Mo ranti pe nitori mi
Ni O se ku ni Kalfari
mf Jesu nto mi l‘osan l‘oru
Jesu nto mi l‘ona gbogbo
O je Ore toto fun mi,
Tori mo ranti Kalfari.

2 Mo ti feran ase Re to;


Mo fe k‘owo Re ma to mi,
cr Ife rere Re ti dun to
T‘O fihan l‘oke Kalfari.

3 f Mo nlo pel‘okan diduro


Ninu Kristi Olugbala;
Ni igbekele pe laipe
Uno ri Jesu ti Kalfari.
Amin.

762 8.8.8.6. & Ref.


E lakaka lati wo oju-ona koto
Lk. 13:24.

1 mf M o nja lati t‘ona iye,


Lati tubo sunmo Jesu;
L‘akoko ‘danwo un o bebe
Fun ore-ofe Re
f A! ore-ofe yi,
To kun fun iyanu;
Ore-ofe yi to fun
Ohun gbogbo fun mi.

2 Ohun Re tun npe mi pada,


‘Gba mo si fara mi fun U,
Mo ri ogo Re lara mi,
Ogo or‘ofe Re

3 mp Mo nwa Krist‘ mi lor‘ekun mi


Ore-ofe li ebe mi
‘Gbana li omije, mo ri
Ogo or‘ofe Re
Amin.

763 7.6.7.6.D.
We mi nu kuro ninu ese mi.
OD. 51:2.

1 mf Mo kese mi le Jesu,
Odagutan mimo,
O ru gbogbo eru mi,
O so mi d‘omnira
Mo ru ebi mi to wa
K‗O we eri mi nu,
cr K‘eje Re iyebiye
Le so mi di mimo.

2 mf Mo k‘aini mi le Jesu,
Tire l‘ohun gbogbo;
O w‘arun mi gbogbo san,
O r‘emi mi pada,
Mo ko ibanuje mi,
Eru at‘aniyan
f Le Jesu, O si gba mi,
mp Ogba irora mi.

3 mf Mo gbokan mi le Jesu,
Okan are mi yi;
cr Ow‘otun Re gba mi mu,
Mo simi l‘aya Re,
Mo fe oruko Jesu
Imanueli, Krist‘
Bi orun didun yika
Ni oruko Re je

4 mf Mo fe ki nri bi Jesu,
p Ni rele at'ife;
mf Mo fe ki nri bi Jesu,
p Omo mimo Baba;
mf Mo fe ki mba Jesu gbe
Larin egbe mimo,
cr Ki nkorin iyin titi,
Orin t'angeli nko
Amin.

764 C.M. & Ref.


Nitori Emi ni Olorun re:
Emi yoo fun o ni okun Isa. 41:10.

1 mf E mi ko le sai l‘agbara,
Lati j‘olododo;
Tori Olorun mbe fun mi,
Lati ran mi lowo.
cr A! mba le gbeke mi le E
Bi On ti wa nitosi,
mf On ko ni sai ran mi l‘owo
Y‘O si pese f‘aini mi.

2 mf Nko le sai ma l‘ore toto


Jesu ni ore mi;
cr B‘ore miran ko tile si,
Jesu fe mi d‘opin.

3 Nko le sai ma l‘ayo giga,


Ayo Re wa n‘nu mi,
Kukuru ni ayo t‘aye,
Tire wa titi lae

4 mf Nko le sai ma l‘ohun gbogbo,


Olorun je gbogbo;
Mo nkorin ‘yin Re lojojo,
Mo npe oruko Re.
Amin.

765 11.7.10.8. & Ref.


Gbe agbelebu ki o si ma to mi lehin
Mk. 10:21.

1 mf O n‘agbelebu ni mo ni ba lo ‘le,
Ko tun si ona mi mo;
Un ko ni de enu ona ogo na
Bi mo ba so ona yi nu
cr Ona agbelebu yi,
L‘o lo si ile ogo (tara)
O dun ki nmo bi mo ti nrin lo pe,
On nikan l‘ona ile.

2 mf Mo ni lati rin l‘ona ta f‘eje won,


Ona t‘Olugbala rin;
Bi mo ba fe g‘oke lo si orun
Nibiti okan gbe nsimi.

3 mp ‘Gbana uno ki aye pe, ―O digbose‖


Un ko tun rin l‘ona re mo;
‘Tori Kristi duro l‘enu ona
O si npe mi pe, ―Wa ma bo‖.
Amin.

766 11.8.11.8. & Ref.


Pelu ipinnu okan, efi ara mo Oluwa
Ise. A. 11:23.
1 mf ‘G bati o ba nlo s‘ile ‘simi orun,
Sunmo Jesu titi d‘opin;
‘Tori Oun ni Oluto t'O m‘ona ju,
Sunmo Jesu titi d‘opin.
f Fara mo Jesu, Fara mo Jesu,
Sunmo Jesu titi d‘opin;
Losan tabi l‘oru mase ya kuro,
Sunmo Jesu titi d‘opin.

2 cr Mase ronu wahala at‘iponju,


Sunmo Jesu titi d‘opin,
O dara lati ri ojurere Re,
Sunmo Jesu titi d‘opin.

3 Ki o ba le bo lowo Ofa esu,


Sunmo Jesu titi d‘opin;
Gbe apata igbagbo fun isegun,
Sunmo Jesu titi d‘opin,

4 f Awa y‘o dele wa orun nigbose,


Sunmo Jesu titi d‘opin;
Nibiti a ki wipe ―o digbose‖
Sunmo Jesu titi d‘opin.
Amin.

767 9.8.9.7. & Ref.


A WON ogun ti mbe li orun si nto lehin
Ifi. 19:14.

1 mf Gbo iro li opopo aye


Bi ti igbi omi okun,
Ti nfi agbara re ru s‘oke
T‘o si nkolu ebute.
Gbo iro ese omo ogun
Bi won ti nrin lo li ona na,
Are mu won fun ‘se at‘irin ajo
Ati ija kikoro;
Sugbon won gbagbo, won tejumo
Ona na t‘awon mimo ti nrin,
Bi won ti nlo ni ‘gbagbo
Won ndagba n‘nu Olorun Alaye

2 Won ntesiwaju pelu ‘gbagbo


Ti ekokeko ko le mi;
Won gbagbo pe oro Olorun
Le pese faini gbogbo.

3 cr Dapo mo won, aye wa sibe,


Duro de ‘bukun Olorun;
Oun ni ‘reti gbogbo agbaye
Lati sise ododo.
Amin.

768 7.7.7.3.
E ma sona, ki e si ma gbadura,
ki eyin ki o ma ba bo sinu idewo.
Mat. 26:41.

1 mf Kristian mase jafara;


Gbo b‘angeli re ti nwi:
Ni arin ota lo wa,
Ma sora.

2 f Ogun orun apadi,


T‘a ko ri nko ‘ra won jo;
Won nso ijafara re,
p Ma sora.

3 mf Wo ‘hamora orun re,


WO l‘osan ati l‘oru;
Esu ba, o nd‘ode re;
p Ma sora.

4 mf Awon to segun saju,


Won nwo wa b‘awa ti nja;
cr WON nfi ohun kan wipe:
Ma sora.

5 f Gbo b‘Oluwa re ti wi,


di Eni ti iwo feran;
p F‘oro Re si okan re;
p Ma sora

6 mf Ma sora bi enipe
Nibe ni ‘segun re wa,
Gbadura fun ‘ranlowo,
Ma sora.
Amin.

769 1.1.1.1.
Je alagbara ninu Oluwa, ati ninu
agbara ipa Re. Efe. 6:10.

1 mf Larin ewu at‘osi,


Kristian, ma tesiwaju;
f Roju duro, jija na,
K‘ounje ‘ye mu o lokun.

2 f Kristian, mate siwaju,


cr Wa ka d‘oju ko ota;
E o ha beru ibi?
S‘e mo ‘yi Balogun yin?

3 f Je ki okan yin ko yo,


Mu ‘hamora orun WO;
cr Ja, ma ro pe ogun npe,
Isegun yin fere de.

4 mp Maje k‘inu yin baje,


Oun y‘O n‘omije yin nu;
Mase je k‘eru ba yin,
B‘aini yin lagbara yin.

5 mf Nje e ma tesiwaju,
cr E o ju asegun lo;
B‘op‘ota doju ko yin,
Kristian, e tesiwaju.
Amin.

770 C.M.
Jesu wipe: Emi li ona ati otito ati iye.
Jn. 14:6.

1 mf Iwo l‘ona; odo Re ni


Awa o ma sa bo;
Awon t‘o nsaferi Baba
Yoo wa s‘odo Re

2 F IWO l‘Oto, oro Tire


mf L‘o le f‘ogbon fun wa;
IWO nikan l‘o le ko wa,
T‘o si le we okan.

3 F IWO n‘lye; iboji Re


Fi agba Re han;
Awon t‘o gbeke won le O,
Won bo l‘owo iku.

4 F IWO L‘Ona, Oto, Iye,


mf Jek‘a mo Ona re;
K‘a mo otito at‘iye,
T‘ayo re ko l‘opin.
Amin.

771 8.7.8.7
0 si wi fun won pe: e ma to mi lehin,
lojukanna nwon si nto O lehin.
Mat. 4:19 & 20.

1 mf Jesu npe wa l‘osan, l‘oru


Larin irumi aye;
cr Lojojumo la ngb‘ohun Re
p Wipe, ―Kristian, tele mi‖.

2 mf Awon Apostel igbani


Ni odo Galili ni;
Won ko ile, ona sile,
Gbogbo won si nto leyin.

3 Jesu npe wa kuro ninu


Ohun aye asan yi;
Larin afe aye O nwi;
p Pe: ―Kristian, e feran Mi‖.

4 mf L‘arin ayo at‘ekun wa,


L‘arin lala on ‘rorun:
Tantan l‘O npe l‘ohun rara
p Pe: ―Kristian, e feran Mi‖.

5 mp Olugbala, nip‘anu Re,


cr Je ki a gbo ipe Re;
F‘eti ‘gboran fun gbogbo wa,
K‘a fe O ju aye lo.
Amin.

772 S.M.
Enikeni ti a ti pa Olorun bi ki i dese
I Jn. 3:9.

1 mf Ki nma batun d‘ese


Ti Olorun mi ko;
Oluwa, se atunda mi '
Si s‘okan mi d‘otun.

2 Nigbana l‘okan mi
Yo korira egbin;
B‘lfe Re ti ya si mimo
Ki o si d‘ese mo.

3 Ofin Re mimo ni,


Jesu jo li ko mi;
cr Ofin Emi nipa iye
Jo ko si aye mi.

4 Gbin sinsin sinu mi,


Ko ma le sipo lae;
Ofin ‘dande kuro n‘n‘ ese
Ofin pipe t‘ife.
5 mf K‘iwa Re je temi,
Iwa ailaba won;
Mo fa okan mi s‘odo Re.
Ni wakati gbogbo.

6 f ‘WO ni ‘ye emi mi,


Oludande aye;
Mu ife Baba Re orun
Se ninu aye mi.
Amin.

773 C.M.
Da aya titun sinu mi, Olorun:
ki o si tun okan diduro sinsin se
sinu mi. OD. 51:10.

1 mf Olorun! mo mo O n‘temi,
Nki o fi O sile
Tit‘ini mi yo di Tire
T‘ao si SO mi d‘otun.

2 mp Mo fiwariri di O mu,
Nki o fi O sile;
Titi un o duro n‘nu ‘gbagbo.
Ti uno mo ore Re.

3 ‘Gbawo l‘akoko na yo de
Ti ‘WO yo gbe n‘nu mi;
Emi iye at‘agbara,
At‘omnira pipe?

4 mf Jesu, tan ife asegun


Si inu okan mi,
K‘ese mi mase yapa mo,
K‘o mule ninu Re

5 f Ina mimo Iba je le


Gberan ni inu mi;
K‘o jo Idaro 'fekule,
K'o si Yo apata

6 mp Ina iba je sokale,


K‘o run gbogb‘ ese mi:
Wa Emi Mimo je ‘pe mi,
Emi bi ina, wa!

7 mp Ina atunse, wonu mi,


Tan ‘mole s‘okan mi,
cr Fi emi Re kun gbogbo re,
mp K‘o si ya si mimo
Amin.

774 C.M.
Emi o fi okan titun fun yin pelu.
Esek. 36:26.

1 mf Mo fe okan laini ese,


Lati yin Oluwa;
di Okan li o mo eje Re
T‘a ta sile lofe

2 mf Okun suru, to si tutu,


Ite Oludande,
Nibi Kristi nikan nsoro,
Ti O nikan njoba.

3 mp Okun ‘rele ti nsa fese.


To gbagbo, to si mo;
T‘iku tab‘iye ko le ya
Lodo Krist‘ ti ngbe be.

4 f Okan titun patapata,


To kun fun ‘fe orun;
Pipe, tito, mimo, rere
Aworan Re, Jesu.

5 mf Oluwa, f'iwa Re fun mi


Jo sokale kankan;
Ko oko titun s‘aya mi,
p Oruko Re t‘ife
Amin.

775 L.M. & Ref.


Sugbon eniti o baforiti titi de opin oun
na li ao gbala Mat. 24:13.

1 mp O kan aare ile kan mbe


L‘ona jinjin s‘aye ese;
Ile t‘ayida ko le de,
Tani ko fe simi nibe.
mf Duro, roju duro, mase kun (2)
Duro, duro, sa roju mase kun.

2 mp Bi wahala bo o mole,
B‘ipin re l‘aye ba buru,
W‘oke s‘ile ibukun na;
Sa roju duro mase kun:

3 mp Bi egun ba wa l‘ona re,


Ranti ori t‘a f‘egun de;
B‘ibanuje bo okan re,
Oti ri be f‘ Olugbala.

4 cr Ma sise lo, mase ro pe,


A ko gb‘adura edun re;
mf Ojo isimi mbo kankan;
Sa roju duro, mase kun!
Amin.

776 L.M.
Bi enikan ba nfe lati to mi lehin ki o
se ara re ki o si gbe agbelebu re.
Mat. 16:24.

1 f Gb‘agbelebu re ni Krist‘ wi
B‘o ba fe s‘omo eyin Mi;
Se ‘ra re, ko aye sile,
Si ma fi ‘rele tele Mi.

2 mf Gb‘agbelebu re, ma je ki
Iwuwo re fo o laya,
cr Ipa Re y‘ogb‘emi rero,
Y‘o m‘okan at‘apa re le.

3 mf Gb‘agbelebu re matiju,
Ma je k‘okan were re ko;
p Oluwa ru agbelebu
Lati gba o l‘owo iku.

4 mf Gb‘agbelebu re n‘ipa Re,


Rora ma la ewu ja lo;
cr Y‘o mu o de ile ayo;
Y‘o mu o segun iboji.

5 mf Gb‘agbelebu re, ma tele,


Mase gbe sile tit‘iku
Eni t‘O ru agbelebu
cr L‘o le reti lati d‘ade.

6 mf ‘Wo Olorun, Metalokan,


L‘a o ma yin titi aye;
Fun wa, k‘awa le ri n‘ile
Ayo orun ti ko lopin.
Amin.

777 D.S.M.
Sugbon e bowo fun Kristi bi Oluwa li okan
yin. I Pet. 3:15.

1 mf Jesu, agbara mi,


IWO l‘aniyan mi;
Emi fi igbagbo woke,
Iwo l‘O ngbadura;
Jeki nduro de O
Ki nle se ife Re;
Ki IWO Olodumare
Ko SO mi di otun.

2 mf Fun mi l‘eru orun,


Oju to mu hanhan;
T‘y‘o wo O n‘gb‘ese sunmole,
Ko ri b‘esu ti nsa;
Fun mi ni emi ni
T‘O ti pese tele;
f Emi to nduro gangan lae,
T‘o nfadura sona.

3 Mo nfe f‘owo to to
Fun oruko nla Re.
Ki nma ka ohun miran si
Lehin eyi nikan;
Ki iyin Re aiku
Je oran edun mi;
Ki nma dupe, ki gbogb‘aye
Ma yin or‘-ofe Re

4 mf Mo gbeke l‘oro Re
‘WO l‘o leri fun mi;
Iranwo at‘igbala mi
Y‘o t‘odo Re wa se;
Sa je ki nle duro,
K‘ireti mi ma ye,
Tit‘Iwo o fi m‘okan mi
WO ‘nu isimi Re
Amin.

778 7.6.7.6.D.
Bi enikeni ba nsin mi ki o ma to mi
lehin. Jn. 12:26.

1 mp Jesu, mo ti se ‘leri
Lati sin O d‘opin;
Ma wa l‘odo mi titi,
Baba mi, Ore mi;
Emi k‘y‘o beru ogun
B‘IWO ba sunmo mi,
Emi ki yo si sina
B‘O ba f‘ona han mi.

2 Je ki nmo p‘O sunmo mi


Tori ‘baje aye;
Aye fegba okan mi,
Aye fe tan mi je;
Di Ota yi mi kakiri,
L‘ode ati ninu;
Cr Sugbon Jesu sunmo mi,
Dabobo okan mi.

3 p Jeki nma gbo ohun Re,


B‘O ti mba mi soro,
Larin iji idanwo,
ASO at‘agidi;
CR SO, mu ko da mi loju,
K‘okan mi ni ‘janu;
SO, si mu mi gbo Tire,
‘WO Olutoju mi.

4 mf Jesu,‘WO ti se‘leri
F‘awon t‘o tele O,
Pe ibikibi t‘O wa
N‘iranse Re yo wa;
Jesu, mo ti se ‘leri
Lati sin O dopin,
Je ki nle to O leyin,
Baba mi, Ore mi.

5 p Jeki nma ri ‘pase Re


Ki nle ma tele O;
Nipa ‘gbara Re nikan,
Ni mo le tele O:
To mi, pe mi, si fa mi,
Di mi mu de opin;
Si gba mi si odo Re,
Baba mi, Ore mi.
Amin.

779 8.7.8.7.8.8.8.7.8.7.
Iwo ba wa kalo, awa o si pe o ni ire.
Num. 10:29.

1 ―E yin ero, mbo l e nlo,


T‘eyin t‘opa l‘owo yin‖
A nrin ajo mimo kan lo,
Nipa ase Oba wa,
Lori oke on petele,
A nlo s‘afin Oba rere,
A nlo s‘afin Oba rere,
A nlo s‘ile to dara,
A nlo s‘afin Oba rere,
A nlo s‘ile to dara.
2 Eyin ero, e so fun ni,
Ti ‘reti ti eyin ni,
ASO mimo, ade ogo,
Ni Jesu y‘O fi fun wa;
Omi iye lao ma mu;
A o ba Olorun wa gbe,
A o ba Olorun wa gbe,
N‘ile mimo didara;
A o ba Olorun wa gbe
N‘ile mimo didara.

3 Ero, a le ba yin kegbe


L‘ona ajo s‘ile na
Wa, ma kalo, wa ma kalo,
Wa, si egbe ero wa,
Wa, e mase fi wa sile,
Jesu nduro, O nreti wa,
Jesu nduro, O nreti wa
N‘ile mimo to dara;
Jesu nduro, O nreti wa
N‘ile mimo to dara
Amin.

780 C.M
Enoku si ba Olorun rin.
Gen. 5:24.
1 mp E mi ‘ba le fiwa pele
Ba Olorun mi rin;
Ki n ni imole ti nto mi
S‘odo Od‘agutan!

2 Ibukun ti mo ni ha da
‘Gba mo ko mo Jesu;
Itura okan nu ha da
T‘oro Kristi fun mi

3 Alafia mi nigbana,
‘Ranti re ti dun to!
Sugbpn won ti f‘aro sile
Ti aye kole di.

4 f Pada, Emi mimo, pada


Ojise itunu;
Mo ko ese t‘o bi O n‘nu,
T‘o le O l‘okan mi.

5 O sa ti mo fe rekoja,
Ohun to wu ko je,
Ba mi yo kuro l‘okan mi,
Ki nle sin ‘Wo nikan.

6 Beni un o fifara bale


p Ba Olorun mi rin;
‘Mole orun yo ma to mi
S‘odo Od‘agutan.
Amin.

781 L.M.
Enikeni ti o ba tiju mi,
Omo eniyan yio tiju re pelu.
Mk. 8:38.

1 mf Jesu, O hale je be pe
p Ki eni kiku tiju Re
Tiju Re, ‘Wo t‘angeli nyin,
Ogo Eni nran titi lae.

2 Ki ntiju Jesu! O san pe


Ki ale tiju irawo;
Oun ni ntan imole orun
Sinu okan okunkun mi.

3 Ki ntiju Jesu! bakanna


Je ki oru tiju osan;
Okun oru bo okan mi
K‘irawo oro to tuka.

4 Ki ntiju Jesu! Ore ni,


Eni mo nwo lati d‘orun!
B‘o ba ri be, k‘oju ti mi,
Pe nko b‘owo foko Re mo

5 Ki ntiju Jesu! mo le se,


Bi nko ba l‘ese t‘ao wenu,
Ti nko l‘edun, ti nko l‘eru,
Ti nko fe ‘re tab‘igbala.

6 Un o ha hale lasan n‘gbana


Pe mo l‘Olugbala t‘a pa
f A! k‘eyi je isogo mi
Pe: Kristi ko si tiju mi
Amin.

782 15.9.15.9. & Ref.


Awon eni irapada Oluwa yio pada,
nwon o wa si Sioni ti awon ti orin.
Isa. 35:10.

1 mf O ti dun to lati mo Jesu


Eni t‘O gba mi la,
‘Jojumo Okan mi kun f ayo,
Ayo ni lati ri pe O mba ihi lo sibikibi,
‘Jojumo ogo ni f‘Oluwa.
f O ti dun to lati ma ba rin,
O ti dun to lati ma ba rin,
Y‘O ma se amona mi
N‘nu ‘mole at‘okunkun;
O ti dun to lati ma ba rin.

2 mf O ti dun to ki O wa nitosi nigba idanwo,


Ka sa gbagbo ka si gbadura;
O ti dun to ki a ma gbe n‘nU
Kristi nigbakugba
Y‘O ma fi ogo orun kun wa.

3 mf Y‘o ti dun to lati pade Re l‘ebute ogo na


Awa yo pade l‘aipinya mo;
Orin ogo, ogo, ogo la o ma ko titi lae
Ni ilu ologo ti Baba. Amin.

783 L.M
Iyin Oluwa yio ma wa li enu mi titi lae.
OD. 34:1.

1 mf Olorun, gbogbo ojo mi


L‘emi o fi ope yin O;
Orin mi yo ba ‘mole ji,
Yo mu okun oru tuka.

2 mp B‘aniyan fe ba ‘simi je
T‘edun fe ba mi n‘inu je,
mf Orin iyin Re t‘emi nko
Yo ko ‘kedun na n‘ijanu.

3 mp ‘Gba ‘ku ba bori ara mi,


Ti gbogbo ipa ede pin;
f Oju mi yo kun fun ayo
At‘ope t‘emi ko le so.

4 Sugbon ‘gbat‘ija ‘keyin tan


T‘ago ara ba bo sile;
Tayotayo ni un o goke
Lati gbe orin ti orun.

5f Emi o ko orin giga


Ti ndun larin ode orun:
Em‘o f‘ayo to apere
Awon angel to y‘ite ka.
6f Uno ma sin O tayotayo,
Bi emi mi yo ti wa lae;
Ise didun, orin giga,
Yo je ipin ayeraye.
Amin.

784 L.M
Sugbpn awon ti o ba duro de
Oluwa yio tun agbara Won se.
Isa. 40:31.

1 mf Ji, okan wa, k‘eru wa lo;


Ki ero ijaya wa lo;
Ji, ko sure ije t‘orun,
Ko si gbe ‘gboya ayo WO.

2 Loto, ona na kun f‘egun


Are si mu emi eniyan;
Sugbon won gbagbe Olorun
Ti n f‘agbara bo eniyan Re.

3 Olodumare, ipa Re
Leke, o mbe l‘otun titi,
Sinsin lo duro, bi odun
Ti nyipo li ainipekun.

4 Lodo Re n‘isun na ti nsan


L‘okan wa yo ma mu, titi
Gba‘won to gbekele‘pa won
Yo yo danu, yo re, yo ku.

5 B‘idi ti nyara fo l‘orun


Lao goke lo s‘ibugbe Re;
Okan wu yo fiye ‘fe fo
Laise are lona orun.
Amin.

785 C.M.
Ki emi ki o le ma wo ewa
Oluwa ki emi ki o sifi inu didun
wo tempili Re. OD. 27:4.

1 Ohun kan ni un o ma lepa


Pelu gbogb‘emi mi;
Oluwa, se fun ‘ranse Re
Ohun t'Emi Re fe

2 di Fun mi n‘ipo ni ile Re


Larin awon mimo;
Ki nle ma wo oju Re lae,
Ki nwole lese Re

3 mp E wa oju Mi! B‘o ti wi,


L‘aise ijafara
L‘okan mi f‘ayo dahun pe:
cr Un o ma wa oju Re!

4 di Ma ko mi b‘ibanuje de,
T‘adun aye fo lo;
‘Gbat‘ obi on ara ko mi,
Olorun, ranti mi.

5 mp Nigbakugba ni mo ndaku,
Ti nko si ni ‘reti;
Sugbon 'ponju mu mi ranti
Ore Re atijo.

6 mf F‘igboya duro d‘Oluwa


Emi mi, ye beru;
Onidajo ododo mbo,
Irapada re de.
Amin.

786 6.6.6.6.
KO mi li Ona Re, Oluwa.
OD. 27:11.

1 cr Ona Re, Oluwa,


B‘o ti wu ko ha to!
Fi owo Re to mi;
Yan ipa mi fun mi.

2 B‘o rorun, b‘o soro,


Dara dara lo je;
B‘o wo, b‘o to tara,
Lodo Re l‘opin si.

3 cr Nko gbodo yan ‘pin mi;


Nko tile je yan an;
Yan fun mi Olorun:
Ki mba le rin dede.

4 Ijoba ti mo nwa,
Tire ni; jek‘ona
T‘o re ‘be je Tire,
Bi beko un o sina.

5 mp Gba ago mi, fayo


Tab‘ibanuje kun
B‘o ti to l‘oju Re;
p Yan ‘re tab‘ ibi mi.

6 di Yiyan ki se temi
Ninu ohunkohun;
mf Iwo s‘Oluto mi,
Ogbon, ohun gbogbo.
Amin.

787 L.M
Sa wo, awa to O wa. nitori iwo li
Oluwa Olorun wa!
Jer. 3:22.

1 cr Obangiji, gbo ebe mi;


Je ‘feti, ayo, ‘simi mi
Nipa ogo oruko Re
L‘ao fi so mi d'alabukun.

2 di Rere ni O, at‘Ologbon,
‘WO Baba at‘Olorun mi;
Tire l‘emi, n‘ife mimo,
Iranse Re ta f‘eje ra.

3 di L‘are okan, mo tewo mi,


‘WO ni mo nwa, ‘WO ni mo nwo
Bi ero n‘iyangbe ile
Ti nwa odo-omi tutu.

4 mp Bi mba fi O sile, Baba,


Ko le sanfani f okan mi,
Ife ‘dariji l‘ayo mi,
Oju Oluwa n‘iso mi.

5 Un o gb‘owo at‘ohun soke,


Niwon ti mo ba wa laye;
mf Ise yi yo fun mi l‘ayo;
Y‘o gba gbogb‘ojo aye mi.
Amin.

788 C.M
Won sijoko li ese re; olukuluku yio
gba ninu oro re. Deut. 33:3.

1 mf Enit‘eje Jesu we mo
Ko ni fi ese se;
A pa wa mo l‘owo Jesu
A si nrerin ewu.

2 L‘oniruru ona ‘yanu


L‘OWO Re ndabobo
Awon mimo, t‘o gbekele
Igbala Re nikan.

3 cr Woli, Alufa, Oba wa,


A f ayo juba Re,
A si nfirele gba eko
Li abe ese Re.

4 mf Oro Re nfi iye fun ni,


At‘ibukun orun,
cr Jeki mana ife Re bo
Sinu okan gbogbo.
Amin.

789 7.6.7.6.6.6.6.5. & Ref.


Emi kojefi O sile, beni Emi ko je ko o sile
Heb. 13:5.

1 mp Iba j‘afonifoji
‘Bit‘opo ewu wa:
Iba je ninu ‘mole
Ti mo wal‘alafia;
Ohun kan yi daju;
mp B‘okunkun tile su,
mf Bi Jesu pelu mi
Ko s‘ewu nibe
mf Bijesu pelu mi,
Un o lo ‘bikibi;
Ibiti mo ba wa orun lo je
B‘O wa nibe!
Anfani ni lati ru agbelebu Re
Bi Jesu pelu mi
Ko s‘ewu nibe

2 A le ran mi lo lati
Kede oro iye
Fun awon ti o sonu,
Ti npafo n‘nu ese.
Ohunkohun to de,
Nipa Igboran yi
Bi Jesu ba mi lo
Ko s‘ewu nibe.

3 mf B‘Oluwa pe mi lati
Se ise nitosi
Nigbati opo nsise
Fun Un l‘ona jinjin;
Un o fi ‘gbagbo mi han
N‘nu 'dajo Re gbogbo;
Bi On duro Timi,
Ko s'ewu nibe.

4 mf Ki ise fun mi lati


Yan l‘Oluwa lowo;
Temi ni'lati lo si
Ibit‘O ndari mi;
Ibit‘O wu ko je,
Nihin tabi lohun,
Un o wa pelu Jesu
Ni itelorun.
Amin.

790 11.10.11.10.
Oluwa yio fi alafia bu si fun awon
eniyan Re- OD. 29:11.

1 mp Nigbati iji nla nfe lori okun,


T‘ibu yehanna pel‘ariwo nla,
Ni isale okun alariwo yi,
p Idakeroro, alafia njoba.

2 mp N‘isale lohun ariwo igbi ku,


Nibe igbi nkorin titi aye
Bo ti wu kiji oke ti le po to,
Ko le ba simi 'sale okun je.

3 mf Be lokan to mo ife Kristi Jesu,


Tempil mimo kan wa ta ya soto;
Gbogb‘ariwo ohun ibinu aye
p Dakeje l‘ona alafia re.

4 mp Lona jinjin, ariwo ibinu ku,


Ero ife sun jade l‘alafia,
mf Bo ti wu k'iji ti le fo soke to,
f K o le damu okan to ngbe n‘nu
Krist‘.
Amin.

791 7.6.7.6. & Ref.


Efi ayo sin Oluwa. OD. 100:2.

1 f J e oloto s‘Oluwa
T‘O femi Re fun o;
'Ninu ewu at‘ibi,
Je akoni toto.
mf J‘oloto si Jesu,
Gb‘asia Re soke n‘bi gbogbo
J‘oloto si Jesu;
Je akoni lati sise;
cr Nigba t‘ija ba sile
Gbekele Olorun Re;
Sise rere;
mf Korin ‘yin Re;
J‘oloto s‘Oba re.

2 J‘oloto nibikibi,
L‘ojo tabi l‘erun,
Lo sibi to nto O si;
N‘igbadun, n‘irora.

3 mp Mase sise imele.


mf Duro gbonin n‘ipa Re
Mu oro na yara de
Tao ni ‘segun pipe.

4 f J‘oloto bi agbara
Okunkun yi o ka;
Angel Re y‘o ma so o,
Ipa Re l‘orin re.
Amin.

792 C.M. & Ref.


Nigbana ni Jesu ba won wa
si ibi kan ti a npe ni Getsemane.
Mat. 26:36.

1 mf O ba aye mi, mo yin O,


Iwo l‘ogo ye fun;
Ki nma ba gbagb‘ade egun,
cr TO mi si Kalfari.
mf Ki nma gbagbe Getsemane,
Ki nma gbagbe iya t‘O je;
Ki nma gbagbe ife nla Re,
cr TO mi si Kalfari.

2 cr Mu mi ranti iboji Re
Nibiti Iwo sun;
Nibe angeli yi O ka,
Won si nso Oba won.

3 cr Jeki nmu ebun wa fun O


Bi Maria ti se;
Ki nje awoko ife Re,
TO mi si Kalfari.

4 cr Fun mi n‘ife ki nle ma wa


Awon ti ko mo O;
Fi emi Mimo kun ‘nu mi
Ki nso ti Kalfari.
Amin.
793 10.10.108:D
Eyin ni imOle aye. Mat. 5: 1 4.

1 mf Mo fe ki nje imole fun Jesu


Nibikibi, ki nfi ewa Re han,
Ki nma dagba n‘nu ore-ofe Re,
Kinje imole Re l‘aye.
f Ki ntan imole, ki ntan imole,
Ki ntan ‘mole, ife atorunwa;
Ki nma f‘ogo fun l‘osan at‘oru,
Ki nma tan ‘mole fun Jesu.

2 cr Mo fe ki nje imole fun Jesu,


Ninu ayo tabi ibanuje;
Ki nje ‘ranlowo f‘awon t‘eru npa,
Ki nje imole Re l‘aye.

3 Mo fe ki nje imole fun Jesu,


Imole ninu aye ese yi;
Ki nmu awon ti nsako pada bo,
Ki nma gbe oruko Re ga.

4 mf Mo fe ki nje imole fun Jesu,


Ki nfi tayotayo sure ‘je mi;
Ki ngbekele or‘ofe Re nikan
Titi uno fi ri oju Re
Amin.

794 11.11.11.11. & Ref.


Emi o ma too lehin nibikibi ti iwo nlo.
Mat. 8:19.

1 mf ‗Bikibi ti Jesu wa, ewu ko si,


‘Bikibi t‘O to mi si n‘nu aye yi;
cr Laisi Re, ayo turn ko le dun mo mi,
‘Bikibi ti Jesu wa, eru ko si.
f ‘Bikibi.........pelu Re, kil‘a o beru
'Bikibi ti Jesu wa, ewu ko si.

2 mf ‘Bikibi pelu Jesu ayo lo je,


B‘ore miran ko mi,
On ko je ko mi;
cr Bo tile mu mi koju isan ‘danwo,
‘Bikibi pelu Jesu ayo lo je

3 mf ‘Bikibi pelu Jesu ni mo le sun,


B‘o tile jepe okunkun yi mi ka,
f Mo mo pe un o ji si iye pelu Re.
‘Bikibi ti Jesu wa, ile lo je
Amin

795 C.M.
Sugbon emi nlepa nso.
Fili. 3:12.

1 mf T‘Olorun ni emi yo se
Ni gbogbo ona mi;
B‘aye tile dide si mi,
Krist‘ yo j‘aworan mi.

2 T‘Olorun ni emi yo se,


mp Bi ogun tile nja;
‘Gbat‘ara, ore ba KO mi,
mf Baba yo di mi mu.

3 T‘Olorun ni emi yo se
L‘ero at‘iwa mi;
Ninu oro tabi ‘ponju,
Jesu yo s‘asa mi.

4 Ninu idamu aye yi,


L‘emi yo ro mo O;
F‘owo Otun ododo Re
Gb‘ emi omo Re ro.
Amin.

796 L.M.
E lakaka lati wo oju ona koto.
Lk. 13:24.

1 mf E mi nlepa l'ojojumo,
Mo si tun nlakaka pelu;
Ki nle jogun ibugbe na
Ti Jesu ti pese fun mi.

2 mf Emi nnoga l‘ojojumo,


Lati ri pe owo mi te
Ade ologo ti ndan ni;
T‘a se l‘oso fun ayanfe

3 mf Emi nreti l‘ojojumo


Lati gbo ohun ayo ni,
Gbati mba siwo ise pe:
―Bo sinu ayo Baba re.

4 cr B‘aye tabi awon ore


Ba fe fa mi s‘ona egbe,
Jeki nle f‘igboya so pe:
f T‘em‘ni Jesu, un o ba rele.
5 cr ‘WO Oluwa Olorun mi,
Mu mi Segun eran ara,
K‘emi ma ba kose, subu
Kuro lona ile ogo.
Amin.

797 C.M
Gbo adura mi, Oluwa. OD. 102:7.

1 mp Baba alanu t‘o fe wa,


Mo gb‘okan mi si O;
mf Ipa Re t‘o po l‘o gba wa;
Awa nkorin si O.

2 f Tire papa l‘awa fe se,


Gb‘okan wa fun ebo;
O da wa, osi tun wa bi,
A fara wa fun O.

3 Emi Mimo, wa sodo mi,


Fife Oluwa han;
Fun mi k‘emi k‘o le ma rin,
N‘ife Oluwa mi.
Amin.

798 L.M
Ma rin niwaju mi ki iwo
ki o si pe. Gen. 17:1.

1 f M o f‘igbagbo b‘Olorun rin


Orun ni opin ajo mi;
‗‗Op‘at‘ ogo Re tu mi n‘nu,‖
Ona didun l‘ona t‘o la.

2 f Mo nrin l‘arin aginju nla,


p Nibi opolopo ti nu;
Sugbpn on t‘o samona wa,
Ko je ki nsina, ti mba nu.

3 Mo nla ‘kekun t‘on ewu ja,


Aye at‘Esu kolu mi;
Agbara Re ni mo fi la,
Igbagbo si ni ‘segun mi.

4 p Mo nkanu awon ti nhale,


F‘afe aye ti nkoja yi
f Oluwa je ki mba O rin,
Olugbala at‘Ore mi.
Amin.
799 8.7.8.7. & Ref.
A la bukun, fun ni eyin ti n fonrugbin
niha omi gbogbo. Isa. 32:20.

1 f A ra mi fun ‘rugbin rere,


Nigba ifunrugbin wa,
Ma sise l‘oruko Jesu,
Tit ‘Oun o tun pada wa,
ff Nigbana ni a o f‘ayo ka a,
Olukore a ko won si aba.

2 f Olugbala pase wipe,


Sise nigbat‘o j‘osan;
Oru mbowa, mura giri,
Oloko fere de na.

3 T‘agba t‘ewe jumo ke, pe,


‘Wo l‘oluran lowo wa;
Mu ni funrugbin igbagbo,
K‘a s‘eso itewogba.

4 mf Lala ise fere d‘opin,


Owo wa fe ba ere;
B‘O de ninu olanla Re,
Y‘o so fun wa pe, ―siwo‖.
Amin.

800 12.12.13.11. & Ref.


A won ti nla, afonifoji omije lo,
WON SO O di kanga, akoro - ojo si fi
ibukun bo o. - OD. 84:6.

1 mf Un o ba Oluwa mi lo si eba odo


Nibiti omi tutu yoyo nsun jade;
Ibikibi ti o ba to mi si ni uno lo,
Un o ma tele ipase Re de opin.
f Tele, tele, un o ma tele Jesu
‘Bikibi ti O nlo l‘emi o tele
Tele, tele, un o ma tele Jesu
‘Bit‘O ba to mi si l‘emi o ba lo

2 Uno ba Oluwa mi lo si eba odo


cr Nibiti iji nja, ti okunkun si su;
‘Gbati owo Re nto mi, eru kole ba ml,
mf Ko si ewu bi Jesu wa nitosi.

3 f Un o ba Oluwa mi lo si ibikibi,
Leba Oluwa mi li okan mi nle gbe,
Y‘o ma samona mi li ona ti O n ti rin
Titi d‘oke giga, ilu Olorun.
Amin

801 C.M.
To Omode li ona ti yio to.
Owe 22:6.

1 mf Olorun ogbon at‘ore,


Tan ‘mole oto Re,
Lati fona toro han wa,
Lati to sise wa:

2 mf Lati to wa koja larin


Apata l‘agbami;
K‘oko wa le rin laisewu,
K‘agunle l‘alafia.

3 mf Ore-ofe Re l‘o ko wa
B‘a ti ko elomi,
A fe to awon omo wa
Ni gbogbo ona Re.

4 mp Ifekufe on ‘gberaga,
K‘a pa run ninu won;
K‘a fi ona mimo han won,
Si Olugbala won.

5 mf K'a ma wo O nigbakugba
Fun apere lati
Ko won n‘iberu on ‘reti;
Fun won l‘ero pipe.

6 mf K‘a fitara pele ko won


Lati ma se ‘gboran;
K‘a ma fikanra se ohun
Ti a ba fife se.

7 cr Eyi l‘a figbagbo bere,


Ogbon lat‘ oke wa!
Ti y‘o feru omo kun won,
Pelu ife mimo.

8 di K‘afa‘fewon kuro l‘afe;


K‘ama fibi bo won;
K‘a jeki okan odo won
Te sodo Olorun.
Amin.

802 8s. 6s.


Bi o se temi ati ile mi,
Oluwa lawa o sin. Jos. 24:15.

1 mf Emi at‘ ara ile mi,


Yoo ma sin Oluwa wa
cr Sugbon emi papa
Yoo fiwa at‘oro han,
Pe mo mo Oluwa t‘orun,
Mo nfokan toto sin.

2 mf Emi o f‘apere ‘re le le;


Un o mu idena na kuro
Lodo om‘ odo mi
cr Un o f‘ise won han ni iwa mi
Sibe n‘nu ‘se mi ki nsi ni
Ola na ti ife.

3 Emi ki y‘o soro gb‘ipe


Emi y‘o pe tu ninu
Om‘eyin Olorun
cr Mo si fe je eni mimo
Ki nsi fa gbogbo ile mi
S‘oju ona orun.

4 cr Jesu, b‘o ba da ‘na fe na


Ohun elo t‘Iwo felo,
Gba s‘owo ara Re
Sise ife rere n‘nu mi
Ki nfi b‘onigbagbo toto
Ti ngbe l‘aye han won,

5 cr Fun mi l‘or‘ofe toto


Nje! Emi de lati jeri
‘Yanu oruko Re
Ti o gba mi lowo egbe
Ire eyi t‘a mo l‘okan
Ti gbogb‘ ahon le so

6 mf Emi t‘o bo lowo ese,


Mo wa lati gba‘le mi la
Ki nwasu ‘dariji:
F‘omo, faya f omo ‘do mi
Lati mu won to‘na rere
Lo si orun mimo.
Amin

803 C.M
Oju Oluwa mbe nibi gbogbo.
Owe. 15:3.
1 mf Ise gbogbo ti awa nse,
Ni Olorun ti ri;
Ero gbogbo t‘o wa ninu,
Ni Olorun si mo.

2 mp A ko le f‘ese wa pamo,
Gbogbo won l‘O ti mo:
A npuro, a ntan ‘ra wa je,
B‘a ro pe ko mo won.

3 Ohun gbogbo han ni gbangba,


Ni oju Olorun;
Okunkun ati imole,
Si ri bakanna fun.

4 f Olorun, je k‘a ranti pe,


Oju re si ri wa;
Si je ki awa k‘o beru'
Lati dese si O.
Amin.

804 10.4.10.4.10.4.
Sugbon ife ti emi ko, bikose
Tire ni ki a fe. Lk. 22:42.

1 mp Oluwa, Olorun mi, se ‘fe Re,


Nki o mi ra,
p Nko ni dide, ki nma ba sesi ta
Owo na nu,
Ti nmu mi ro mo aya
Baba mi
Ni isimi.

2 mf Okan ti nj‘ ijakadi ni Kristi


Nfun l‘agbara;
p Iwaya ija Re oru ‘gbati
Ko s‘enikan,
Ju Baba, at‘angeli rere kan
Ti nt‘U ninu.

3 mp ―Baba, ‘fe mi ko, Tire ni k‘ase


Be l‘Omo wi,
cr K‘eyi j‘asiri wa larin gbogbo
Lala aye,
p K‘a le ro mo aya
Re titi lae
Ni isimi.
Amin.

805 8.8.8.5. & Ref.


Emi ni Alfa ati Omega, li Oluwa wi.
Ifi. 1:8.

1 mf Mo fi gbogbo okan mi tan


Eni t‘O le gb‘emi mi la,
Abo nla, ti ki ye lae
f Oro Re daju.
f ―Emi l‘Alfa, at‘Omega,
Ipilese ati opin,
Ti O wa, t‘O ti wa,
Ti O si mbo wa,
Emi l‘Alfa, at‘Omega,
Ipilese ati opin
Olodumare, Olodumare‖
L‘Oluwa wi.

2 f Okan mi nso pelu ayo.


Ti Eni ti ngbe inu mi,
If‘ eni ti nteloro Re.
Lati mu duro.

3 cr Jehofa, Olorun, gba mi


Lowo ‘yemeji at‘eru;
Fi ‘gbagbo gbigbona fun mi,
M‘okan mi duro.
Amin.

806 7.7.7.7.D.
Olorun mi, eniti emi gbekele OD. 91:2.

1 mf Sa gbekele l‘ojojo.
Gbekele l‘arin ‘danwo,
Bi ‘gbagbo tile kere
Gbekele Jesu nikan.
f Gbekele ni 'gbagbogbo
Gbekele lojojumo;
Gbekele lonakona,
Gbekele Jesu nikan.

2 mf Emi Re ntan Imole


Si ona okunkun mi;
L‘OWO Re, nko le subu
Gbekcle Jesu nikan.

3 B‘ona ba mo un o ko‘rin
cr B‘o ba di, un o gbadura;
Larin ewu, un o kepe,
mf Gbekele Jesu nikan.

4 Gbekele titi d‘opin,


Tit‘aye yo fi koja;
Ti ao si de ‘nu ogo,
Gbekele Jesu nikan.
Amin.

807 7.6.7.6.D.
E gba ajaga mi si orun nyin:
Ki e si ma ko eko lodo mi;
enyin yo si ri isimi fun okan nyin. Mat. 11:29.

1 cr ‘Gbati ‘danwo yi mi ka,


Odo Krist‘ ni mo nlo;
mf Ni okan aya Re ni
Ibi isadi mi;
Mo s‘okan mi paya fun,
O mo gbogb‘ edun mi;
f Bi mo ti nso wonyi,
O m‘edun mi kuro.

2 mp ‘Gbati mo kun fun eru


Ti mo nsunkun pere,
mf O tan ibanuje mi,
O le eru mi lo;
O r‘ewu t‘o yi mi ka,
Ati ailera mi;
f O fun mi l‘ohun ija
Lati segun ese.

3 f L‘odo Kristi ni uno lo,


Nibit‘o wu ko je;
Un o sa ma wo oju Re,
O daju pe un o ri
mp ‘Gb‘ayo tabi ‘banuje
mf Ohun to wu ko je;
Odo Re sa ni uno lo,
Oun y‘o si to mi wa.
Amin.

808 13.13.13.13. & Ref.


Eyi ha ise akoko atigba fadaka
Ati lati gba ASO?
II A. Oba 5:26.

1 mf Oluwa nko bere fun fadaka on wura


Un o jijakadi f‘orun un o si wo ‘nu agbo
N‘nu iwe ijoba Re ti o lewa pupo
So fun mi, Oluwa mi, ooko mi ha wa
nbe
cr Ooko mi ha wa mbe
Ninu iwe nla ni
Iwe ti ijoba Re
Ooko mi ha wa mbe.

2 mp Oluwa ese mi po bi iyanrin okun


Sugbon eje Re, Jesu, tito fun gbogbo re
‘Tori ‘Wo ti se ‘leri ninu oro Re pe,
―B‘ese re pon b‘ododo, un o fo won fun
bi aso.

3 f Ni ‘lu daradara ni, ibugbe imole,


Nibi t‘awon mimo wa, nin‘asp funfun
won
T‘ohun-eri ko le de lati b‘ewa re je
N‘bi t‘awon Angeli nso, ooko mi ha wa
mbe
Amin.

809 6.6.9.6.6.9. & Ref.


1 mf ‘Gbat‘ab‘Oluwarin
N‘nu ‘mole oro Re;
Ona wa yio ti mole to!
‘Gbat‘a ba nse ‘fe Re.
On y‘o ma ba wa gbe,
Ati awon t‘o gbeke won le.
f Sagbekele,
Ona miran ko si
Lati l‘ayo n‘nu Jesu,
Ju pe, ka gbekele.

2 mf Ko s‘ohun to le de,
Loke tabi n‘ile,
To le ko agbara Re l‘oju;
cr Iyemeji, eru,
Ibanuje, ekun
mf Ko le duro, bi a gbekele.

3 f Ko si wahala mo,
Tabi ibanuje.
O ti san gbogbo ‘gbese wonyi
Ko si aro kan mo,
Tabi ifajuro,
Sugbon ‘bukun b‘a ba gbekele.

4 A ko le fenu so
Bi ‘fe Re ti po to
Titi ao fi fara wa rubo;
mf Anu ti On fihan
At‘ayo t‘O nfun ni
Je ti awon ti o gbekele.
5 Ni ‘dapo pelu Re,
Ao joko l‘ese Re.
Tabi ki a ma rin pelu Re,
Awa yo gbo Tire,
Ao jise t‘Oran wa,
f Ma beru, sa gbekele nikan.
Amin.

810 9.9.7.7.9. &Ref.


Ko si enikan ti o ni ife ti o tobiju
Eyi lo pe enikan fi emi re lele
nitori awon ore Re
Jn. 15:13.

1 cr J esu l‘ore to dara julo


‘Gbati ‘gbi aye ba yi lu o;
Y‘O wo okan to gbogbe,
Y‘O si fi agbara fun;
Jesu l‘ore to dara julo
mf Jesu l‘ore to dara ju,
(Jesu l‘ojojo)
(Jesu l‘ore to dara ju)
(Jesu n‘bi gbogbo)
On ki yo je ko subu
Y‘O gbo ‘gbati o ba pe;
Jesu l‘ore to dara julo.

2 mf Ore pataki ni Jesu je,


O f‘alafia kun okan mi,
Ni ‘gbekele apa Re
Nko je beru ibikan;
Jesu l‘ore to dara julo

3 mp Bi ‘banuje tile de ba mi
Ti igbi Jordan si nyi lu mi,
mf Emi ko gbodo beru,
Oluwa mbe nitosi;
Jesu l‘ore to dara julo.,

4 f ‘Gbati a ba dele wa orun


Pelu awon to ti lo saju,
Ao korin l‘ebute Re,
Ao si ma yin I titi;
Jesu l‘ore to dara julo
Amin

811 8.7.8.7.& Ref


E si kiyesii, Emi wa pelu nyin
nigbagbogbo. Mat. 28:20.
1 mf Ibi kan wa, ti mo feran
cr ‘Gba t‘okan mi poruru;
Ki nwa pelu Kristi nikan
Ti O wipe: ―Wa simi‖.
Ki n wa pelu Jesu nikan,
Ki ngbohun jeje Re pe:
f ―Mase beru b‘aye ko o ;
Emi wapelu re‖.

2 mp ‘Gba t‘eru aye ba wuwo,


Ti o si te‘ri mi ba,
Un o lo sodo Jesu nikan
‘Tori ore mi ni Oun.

3 cr ‘Gbati esu nfe lepa mi,


mf Jesu wipe ki nsa wa;
Oun ni abo at‘ore mi,
O j‘ohun gbogbo fun mi.
Amin.

812 L.M.& Ref.


E tujuka, mo ti segun aye. Jn. 16:33

1 f Isegun wa li okan mi,


Nitori Emi ngbe ‘nu mi;
Jeki igbi idanwo de,
Jesu mura lati gba mi.
ff Isegun! Isegun! ‘segun l‘okan mi,
Mo ni isegun nla ‘tori Jesu gb‘okan mi
Isegun! Isegun! bi odo sisan,
Mo ni ‘segun nla ninu eje Jesu.

2 cr Bi ‘ja tile le to si pe,


B‘esu tile b‘okan mi ja;
mf Sibe, mo je alagbara,
f L‘agbara Jesu, ngo segun.

3 f Mo ni ‘segun lori ese,


Mo ni ‘segun lori ‘boji,
Ani iku ko ni ‘pa mo,
ff Aleluya! emi ti la.
Amin

813 8.8.10.7. & Ref.


E tujuka! e ma beru. Mat. 14:27.

1 cr Iji lile le ja yika,


Ki ‘danwo kikan damu mi,
mf Nko je beru b‘Oluwa sunmo mi,
Ti mo ngb‘ohun ife Re
f Ko si nkan to le fo mi laya,
(Fo mi laya)
‘Gba mo ba wa n‘nu Re
(Wa n‘nu Re)
Itunu at‘iranwo mi,
Jesu ta kan mo ‘gi.

2 mp Eniyan le ba mi n‘nu je,


K‘aniyan aye damu mi;
mf Sibe, uno gbekele Oba l‘oke,
Un o fi ‘gbagbo n‘nu Re han.

3 B‘imo yi ko tile ye mi,


mf Sibe, oro Re pa lase,
Ki ngbeke le nipa‘gbagbo nikan,
On yo tun ona mi se.
Amin.

814 11.12.11.10 & Ref.


Nitoto Oun o gba O LOWO ikekun
awon peyepeye. OD. 91:3.

1 mf Eru ‘ji ko ba mi, won yoo dekun;


‘Danwo ko le pa mi, ‘tori mo l‘alafia;
Gbogb‘ohun ti mo ko sile, nko fe mo,
Un o r‘ohun to ju won lo ni Kenan'
f Awon to fe le duro n‘Egypt,
Emi nlo si Kenan‘
Nibi wara at‘oyin, yoo te wa l‘orun;
Lehin ajasegun, ayo at‘alafia je temi;
Okan mi yo simi l‘ebute Re.

2 mf Wahala ko ni pa, ko le duro pe;


Won le wa yi mi ka, un o sa s‘odo Jesu;
Gbogb‘aye le daru, ko si mi titi;
Ko si iji ni ebute Kenan‘

3 mf N‘nu opo ore-ofe, emi fe wa


Li abe ojiji ti Kenan‘ ti o pe;
Gbogbo ‘gbekele mi le ye, ko je nkan;
Ko s‘ohun to le se mi ni Kenan‘ .
Amin.

815 11.11.11.11. & Ref.


A wa ju eniti o segun lo, nipa eniti
o fe wa. Rom. 8:3 7.

1 f A Segun ati ajogun ni a je,


Nipa eje Kristi a ni isegun;
B‘Oluwa je tiwa, a ki yo subu;
Ko s‘ohun to le bori agbara Re.
f Asegun ni wa, nipa eje Jesu;
Baba fun wa ni ‘segun, nipa eje Jesu;
Eni t‘apa felese
Sibe, O wa, O njoba;
ff Awa ju asegun lo,
Awa ju asegun lo.

2 f A nlo l‘oruko Olorun Israel


Lati segun ese at‘aisododo;
Kise fun wa, sugbpn
Tire ni iyin
Fun ‘gbala at‘isegun ta f‘eje ra.

3 f Eni t‘O ba si segun li ao fi fun,


Lati je manna to t‘orun wa nihin
L‘orun yo si gbe imo ‘pe asegun,
Yo wo ‘so funfun, yo si dade wura.
Amin.

816 10.10.10.7. & Ref.


Aye si nkoja lo ati ifekufe re,
sugbpn eniti o ba nse ife Olorun ni yio duro laelae. I Jn. 2:17.

1 mf B ‘aye ba nfa mi pelu ogo re,


Ko s‘ewu, omo Olorun ni mi,
f Owo agbara Re yo di mi mu,
L‘ojo aye mi gbogbo.
Mo l‘ore t‘O npese f‘aini gbogbo,
Mo n‘ile kan loke orun giga,
Wo! Nitori idi eyi na ni,
f Emi se nko Aleluya!

2 cr Emi ko je gbagbe pe lor‘igi,


Ni Omo Olprun gbe ku fun mi;
Ko le saiku lati gb‘okan mi la,
Ko tun si ona miran.

3 mf Un o j‘oloto s‘Oluwa Oba mi,


Uno ma korin ‘yin si nigbagbogbo,
Mo mo pe nikehin;
On yo gba mi;
Lati ma ba gbe titi.
Amin.

817 8.7.8.7.& Ref.


Oluwa ni mo gbeke mi le. OD. 11:1.

1 mf Ki ngbekele Olugbala,
L‘odo Re mo ni ‘bukun,
cr Ki wahala to yi mi ka
Mu mi sunmo odo Re.
f Gbekele lojojumo,
Gbekele Jesu titi;
Ohunkohun to le de,
Gbekele Jesu nikan.

2 mf Ni‘gbekele ojiji Re,


Nigbati orun ko si;
mp Bo ti wu k‘oju orun su,
mf Ife Re yo tan‘mole

3 mf Gbekele imole Re lae


Ko ‘yemeji at‘eru;
Lori oke pelu Jesu
Gbe okan re s‘oke s‘l.
Amin.

818 9.8.9.7. & Ref.


Sugbon emi kiyo gbagbe re.
Isa. 49:15.

1 mp Nigba ti ona mi ba sokun,


Ti ojo ibi ba si de;
cr Emi nranti ileri yi pe:
mf On ko je gbagbe Tire.
On ko je gbagbe Tire,
On ko je gbagbe Tire,
cr Bi ore sa, On wa nitosi,
f On ko je gbagbe Tire.

2 mp Nigbati ‘reti gbogbo ba pin,


T‘iyemeji at‘eru de,
Un o wa ‘simi l‘aya Eni ti,
Ko le je gbagbe Tire.

3 f On ko je gbagbe Tire laelae;


O se owon fun mi pupo,
Lati ‘gbati O ti sokale.
Ti O ngbe ‘nu okan mi.
Amin

819 10.10.11.11
Alabukun fun li awon ti ko ri mi
ti won si gbagbo. Jn. 20:29.

1 f Aigbagbo bila! Temi l‘Oluwa


On O si dide fun igbala mi;
Ki nsa ma gbadura, On O se ‘ranwo,
‘Gba Krist‘ wa lodo mi ifoya ko si.
2 p B‘ona mi ba su, On l‘O sa nto mi,
Ki nsa gboran sa, On o si pese;
Bi iranlowo eda gbogbo saki,
Oro t‘enu Re so, yo bori dandan.

3 mf Ife t‘O fihan ko je ki nro pe


Y‘O fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si nri lojojumo,
O nki mi l‘aya pe, emi o la ja.

4 p Emi o se kun ‘tori iponju,


Tabi irora, O ti so tele,
Mo m‘oro Re p‘awon ajogun ‘gbala,
Won ko le sai koja larin wahala.
Amin.

5 p Eda ko le so kikoro ago


T‘Olugbala mu k‘elese le ye;
Aye Re tile buru ju temi lo;
Jesu ha le jiya, kemi si ma sa?

6 mf Nje b‘ohun gbogbo ti nsise ire,


Fun awon to duro de Oluwa,
B‘ oni tile koro, sa ko ni pe mo,
ff ‘Gba na orin‘segun yio ti dun to?
Amin.

820 10.10.
IWQ o pa a mo li alafia pipe. Isa. 26:3.

1 mp Alafia li aye ese yi?


Eje Jesu nwipe, ―Alafia‖.

2 mf Alafia ninu opo lala?


Lati se ife Jesu, ni simi.

3 Alafia n‘nu igbi ‘banuje?


L‘aya Jesu ni ‘dake roro wa.

4 mp Alafia, ‘gb‘ara wa wa l‘ajo?


Ni ‘pamo Jesu iberu ko si.

5 f Alafia, ba ko tile m‘ola?


A mo pe Jesu joba titi lae.

6 mp Alafia, nigb‘akoko iku?


Olugbala wa ti segun iku.

7 di O to! jakadi aye fere pin,


Jesu y‘O pe wa s‘orun alafia.
Amin.

821 6.6.4.6.6.6.4.
Oju wan wo Oluwa Olorun wa. OD. 123:2.

1 f lgbagbo mi wo O.
Iwo Od‘agutan Olugbala,
p Jo, gbo adura mi,
M‘ese mi gbogbo lo;
cr K‘emi lat‘oni lo
Si je Tire.

2 mf Ki ore-ofe Re
F‘ilera f‘okan mi;
Mu mi tara;
p B‘Iwo ti ku fun mi,
cr A! K‘ife mi si O
K‘oma gbona titi
B‘ina iye.

3 p ‘Gbamonrin l‘okunkun
Ninu ibanuje,
cr S‘amona mi;
So okun di ‘mole;
Pa ‘banuje mi re,
Ki nma sako kuro
Li odo Re

4 p Gba ti aye ba pin,


T‘odo tutu iku
Nsan l‘ori mi,
Jesu, ninu ife,
Mu k‘ifoya mi lo,
Gbe mi d‘oke orun
B‘okan t‘ara.
Amin.

822 6.6.8.6.8.8.
Nitori Emi li Oluwa, Emi koyipada.
Mal. 3:6.

1 mp Nihin l‘ayida wa;


Ojo, erun, nkoja,
di Ile ni nyan ti o si nsa,
‘Tanna dada si nre;
f Sugbon oro Kristi duro:
―Un o wa pelu re‖ ni On wi.

2 mp Nihin l‘ayida wa,


L‘ona ajo orun;
N‘nu ‘gbagbo ‘reti at‘eru,
N‘nu ‘fe s‘Olorun wa:
di A nsalka oro yi si ‘po!
―Un o wa pelu re‖, ni Kristi wi.

3 mp Nihin l‘ayida wa;


cr Sugbon l‘arin eyi:
L‘arin ayidayid‘aye,
f Okan wa ti ki yi;
ff Oro Jehofa kii pada:
―Un o wa pelu re‖, ni On wi.

4 mp Ona alafia;
Imanueli wa,
ff Majemu ti ore-ofe,
Lae, won ki yi pada
cr ―Nki yi pada,‖ l‘oro Baba,
―Mo wa pelu re‖, ni On wi.
Amin.

823 C.M
Ipase Re li a ko si mo. OD. 77:19.

1 mp Ona ara l‘Olorun wa


Ngba sise Re l‘aye;
A nri ‘pase Re lor‘okun,
O ngun igbi l‘esin.

2 mp Ona Re, enikan ko mo,


Awamaridi ni;
cr O pa ise ijinle mo,
Oba awon oba.

3 mp Ma beru mo, eyin mimo,


Orun to su be ni,
cr O kun fun anu yo rojo
Ibukun s‘ori yin.

4 mp Mase da Oluwa l‘ejo


Sugbon gbeke re le;
‘Gbati o ro pe O nbinu,
cr Inu Re yo sio.

5 mf Ise Re fere ye wa na,


Y‘o ma han siwaju;
Bi o tile koro loni,
O mbo wa dun lola.

6 Afoju ni alaigbagbo,
Ko mo ‘se Olorun;
Olorun ni Olutumo,
Y‘O m‘ona Re ye ni.
Amin.

824 12.12.12.7. & Ref.


Nitori Emi li Oluwa, Emi koyipada. Mal. 3:6.

1 mf Olorun t‘O mu Israel la okun ja


Ti O si gba won kuro li oko eru;
Ti O ro ‘jo onje sile lati orun,
f On ni mo ngbadura si.
Okan na loni, okan na loni,
(Bakan na ni Olorun ti mo ngbadura si)
B‘ akoko t‘O sin Israel la okun
(La okun ja)
Omo Re ni un o je, ‘tori oro Re so
Pe, okan na ni Olorun Iyanu loni.

2 mf Olorun t‘O gba Daniel lowo kiniun,


T‘O si yo awon meta n‘nu ina ‘leru,
Eni ti awon irawo ngba Tire gbo,
f On ni mo ngbadura si.

3 mf Olorun t‘O f‘oro Re d‘afefe duro,


T‘O si nso ‘banuje oni d‘ayo lola,
Eni ti O yi okuta ‘boji kuro,
f On ni mo ngbadura si.

4 mf Olorun t‘O wo itanna igbe l‘aso,


Eni t‘O mu omi san n‘iyangbe ile
Ti O we elese mo ninu eri re,
f On ni mo ngbadura si.
Amin.

825 11.11.11.7. & Ref.


SO fun awon omo Israeli ki won ki o tesiwaju. Eks. 14:15.

1 f Kristi Balogun wa niwaju ogun,


B‘O ba ran wa n‘ise a ko ni beru;
Bi ohun t‘O fe se ko tile ye wa,
Sibe ao tele titi.
ff Tesiwaju! l‘ase Oluwa.
Te siwaju si ‘le ‘leri na;
Te siwaju ko orin soke,
Pelu Kristi, isegun daju.

2 f Gbogbo ifeju esu ko le mi wa


Bi Kristi je asa at‘apata wa;
Ao ma fi ida emi bi a ti nlo,
Ao ma tele titi.

3 f E jeki a gbe asia wa s‘oke,


Ibi ko le de ibiti o ba wa,
Kristi, Balogun wa ti segun aye,
A o ma tele titi.

4 f B‘ogunna tile le ko ni pe pari.


Nigbana, ao dapo pe l‘awon mimo
Lati fi ayo ko orin isegun
Bi aba tele titi.
Amin.

826 8.8.8.6.
Abo mi mbe l‘odo Olorun ti O nse
igbala olotito li aya. OD. 7:10.

1 mp Jesu mimo, Ore airi,


Oluranlowo alaini,
N‘nu ayida aye ko mi
K‘emi le ro mo O.

2 Ki nsa n‘idapo mimo yi,


Gba ohun t‘O fe uno kun bi?
B‘okan mi b‘eka ajara
Ba sa le ro mo O.

3 Okan mi t‘are mu pupo


R‘ibi isimi l‘odo Re;
Ibukun ti de s‘okan mi
N‘tori t‘o ro mo O.

4 mf B‘aye d‘ofo mo mi l‘oju,


Ba gba ore at‘ara lo,
di Ni suru ati laibo ‘hun
L‘emi o ro mo O.

5 mp ‘Gba t‘o k‘emi nikan soso,


Larin idamu aye yi,
p Mo gb‘ohun ife jeje na
Wipe, ―Sa ro mo Mi‖.

6 cr B‘are ba fe mu igbagbo,
T‘ireti ba si fe saki,
f Ko si ewu fun okan na
Ti o ba ro mo O.

7 mf Won ko beru ‘rumi aye


Nitori ‘Wo wa nitosi;
Won ko si gbon b‘iku ba de
‘Tori won ro mo O.

8 Ire sa ni l‘ohun gbogbo,


Ko s‘eni le daya fo mi
‘Gba mo fi O s‘Olugbala,
Ti mo si ro mo O.
Amin.

827 L.M.
Nitorina enikeni ti o ba rope on duro
ki o kiyesara ki o ma ba subu.
IKor. 10:12.

1 mp Oluwa, mo f‘eru jewo


Pe, eni rere le subu,
Iyo le so adun re nu,
Ko ma si ri mo titi lae.

2 mf Ki oran mi mase ri be
So okan mi po mo ‘ra-Re;
To mi sori oke lohun,
Koja l‘afonifoji ‘fe.
Amin.

828 11.11.11.11 & Ref


lya igba isisiyi ko ye latifi se aka we ogo
ti a ofi han wa. Rom. 8:18.

1 cr Nigbati ‗gbi aye yi ba nyi lu o,


To si dabi enipe gbogbo re pin,
Ka ibukun re, siro won l‘okokan,
Ise Oluwa yo je ‘yanu fun o
mf Ka ‘bukun re, ka won l‘okokan,
Ka ‘bukun re, wo ‘se Olorun;
Ka ‘bukun re, ka won l‘okokan,
Ka ‘bukun re, wa ri ‘se t‘Olorun se.

2 mp Eru aniyan ha nwo ‘kan re l‘orun!


Ise t‘a pe o si ha soro fun O;
Ka ‘bukun re, ‘yemeji yo si fo lo,
mf Orin iyin ni yo si gb‘enu re kan.

3 ‘Gbat‘ o ba nwo awon oloro aye,


Ronu oro ti Jesu ti se leri;
Ka ibukun re, owo ko le ra won,
Ere re l‘orun ati ‘le re l‘oke.

4 mp Ninu gbogbo ayidayida aye,


mf Mase foya, Olorun tobi julo;
f Ka ‘bukun re, awon angel‘ yo to o
Won yo si ran o lowo titi d‘opin.
Amin.

829 L.M.&Ref.
E mayo ninu Oluwa nigbagbogbo.
Fili. 4:4

1 f Eyo n‘nu Oluwa, e yo,


Eyin t‘okan re se dede;
Eyin t‘o ti yan Oluwa,
Le ‘banuje at‘aro lo
ff E yo! E yo!
E yo n‘nu Oluwa, e yo!
E yo!E yo
E yo n‘nu Oluwa, e yo!

2 f E yo ‘tori On l‘Oluwa,
L‘aye ati l‘orun pelu;
Oro Re bori ohun gbogbo,
O l‘agbara lati gbala.

3 cr ‘Gbat‘ e ba nja ija rere,


Ti ota fere bori yin;
mf Ogun Olorun t‘e ko ri
Po ju awon ota yin lo.

4 mp B‘okunkun tile yi o ka,


Pelu isudede gbogbo,
mf Mase je k‘okan re damu,
Sa gbekel‘Oluwa d‘opin.

5 f E yo n‘nu Oluwa, e yo,


E korin iyin Re kikan;
Fi duru ati ohun ko
Aleluyal‘ohungoro.
Amin.

830 10.10.10.10 & Ref


Ninu aye, enyin o ni iponju;
Sugbon e tujuka; Mo ti segun aye. Jn. 16:33.

1 pp Ibanuje po fun wa l‘aye yi,


Ekun m‘oju wa tutu, o si su;
mp ‘Banuje at‘aro ko si l‘ohun
cr Ni ‘le na nibiti ko si odun.
Tabi ibanuje at‘ekun;
mf Ao gbe ‘be l‘alafia ayo wa yo po
Ni ‘le na nibiti ko si odun.

2 cr Bi a nsise, t‘ise wa ko si han,


A ni ‘gbagbo, ba ko tile r‘eso;
mf Sugbpn Oluwa y‘o f‘asiri han
Ni ‘le na nibiti ko si odun.

3 mf A tujuka li enu ise wa,


A gbagbe 'banuje at‘eru wa;
‘Tori bi nkan aye ba koja lo,
A o gbe nibiti ko si odun.
Amin.

831 9.9.9.8.& Ref.


Ore ofe mi to fun o. II Kor. 12:9.

1 Awon to gbekele Oluwa


Yio bori igbi idanwo;
Nitori ileri yi daju,
―Ore-ofe mi to fun o‖
Ore-ofe mi to fun o
Ore-ofe mi to fun o
Ore-ofe ti ko l‘egbe:
Ore-ofe mi to fun o.

2 Manna lat‘orun li eyi je


Fun awon ero mimo l‘ona
T‘eru npa, to si nwa isimi,
―Ore-ofe Mi to fun o‖

3 Larin ire ije ti iye,


Bi are tile mu o subu:
Tun dide, ko si te siwaju;
―Ore-ofe Mi to fun o‖

4 Idanwo ati iyemeji


At‘ewu ko le ba ni l‘eru;
‘Tori mo di ileri yi mu:
―Ore-ofe Mi to fun O‖.
Amin.

832 C.M. & Ref.


Oluwa yio ma to o nigbagbogbo. Isa. 58:11.

1 mf Mase foya ohunkohun,


Olorun y‘O to o:
Ma gbe ibi ikoko Re,
Olorun y‘O to o .
f Olorun y‘O t o o;
Lojojumo, l‘ona gbogbo;
On y‘O ma toju re,
Olorun y‘O to o .
2 cr ‘Gbati okan re ba damu,
mf Olorun y‘O to o;
cr ‘Gbat‘ ewu ba wa l‘ona re
mf Olorun y‘O to o .

3 On y‘O pese fun aini re,


Olorun y‘O to o;
Y‘O si mu ibere re se,
Olorun y‘O to o.

4 mf B‘o ti wu k‘idanwo po to,


Olorun y‘O to o;
Simi, alare l‘aya Re,
Olorun y‘Oto o.
Amin.

833 6.4.6.4.6.6.4.
Fa mi lo ni ile ti o teju.
OD. 143:10.

1 mf Un o sunm‘O,Olorun,
Un o sunm‘ O
cr Bo tile se‘ ponju
L‘O mu mi wa,
Sibe, orin mi je;
Un o sunm‘O, Olorun,
Un o sunmo O.

2 cr Ni ona ajo mi
B‘ile ba su;
Bi okuta si je
Irori mi;
Sibe, n‘nu ala mi,
Un o sunm‘O, Olorun,
Un o sunmo O.

3 Nibe, jeki nr‘ona


Tolo s‘orun;
Gbogb‘ohun t‘O fun mi
Nin‘ anu Re,
Angel‘ lati pe mi,
Sunm‘O, Olorun mi,
Un o sunmo O.

4 mf Nje ‘gbati mo ba ji
Em‘o yin O;
Un o fakete mi se
Betel fun O;
cr Be, ninu osi mi,
Un o sunm‘O, Olorun,
Un o sunmo O.

5 f ‘Gba mba fi ayo lo


S‘oke orun
Toga ju orun lo
S‘oke giga;
Orin mi yio je!
Un o sunm‘O, Olorun,
Un o sunmo O. Amin.

834 7.7.7.7.D.
Ki a mase ri pe emi nsogo bikose
ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa. Gal. 6:14.

1 mp Mo mbo nib‘agbelebu,
Emi abosi julo;
Mo ka gbogbo nkan s‘ofo
Lati ri ‘gbala kikun.
cr Mo gbekele O, Jesu
Odagutan Kalfari,
di Mo fi ‘rele teriba,
Gba mi, Jesu, loni yi.

2 mf Mo gbekele ‘leri Re,


At‘agbara eje ni,
mp Mo pon ara mi l‘oju,
Mo nru agbelebu Re.

3 mf Jesu fi ayo kun mi,


O si so mi di pipe;
Mo ni ilera pipe;
f Ogoni f‘Od‘agutan.
Amin.

835 C.M
Oluwa ranti mi. Lk 23:42
1 mf Iwo low‘ Eni t‘ire nsan
Mo gb‘okan mi si O
di N‘ibanuje at‘ise mi,
p Oluwa, ranti mi.

2 mp ‗Gba mo nke ‗rora l‘okan mi


T‘ese wo mi lorun
cr Dari gbogbo ese ji mi,
p Ni Ife, ranti mi.

3 mp Gba ‘danwo kikan yi mi ka


Ti ibi le mi ba,
cr Oluwa fun mi l‘agbara,
p Fun rere, ranti mi.
4 mp Bi‘tiju at‘egan ba de
N‘tori oruko Re
mf Un o yo s‘egan, un o gba ‘tiju
B‘IWO ba ranti mi.

5 di Oluwa ‘gba iku ba de,


Em‘o sa ku dandan,
p K‘eyi j‘adura ‘gbehin mi:
―Oluwa, ranti mi‖.
Amin.

836 S.M.
A wa sokun nigbati awa ranti Sion.
OD. 137:1.

1 mf Jina s‘ile orun,


S‘okan aya Baba,
Emi ‘bukun wa, Mon daku
Mu mi re ‘bi ‘simi.

2 Mo fi duru mi ko,
S‘ori igi Willo;
Un o se korin ayo, ‘gbati
‘WO koi t‘ahon mi se.

3 Emi mi nlo s‘ile,


A! mbale fo de ‘be;
Ayun re nyun mi
‘WO Sion Gba mo ba ranti re

4 cr S‘odo Re mo nt‘ona
To kun fun isoro;
‘Gbawoni un o ko j‘aginju,
Dele awon mimo.

5 mf Sunmo mi, Olorun,


‘WO ni mo gbekele,
Sin mi l‘aginju aye ja,
Ki ndele nikeyin.
Amin.

837 7.7.7.5.
Lati inu ibu wa li emi kepe O,
Oluwa. OD. 130:1.

1 ‗Wo t‘O ku ni Kalfari,


‗Wo t‘O mbebe f‘elese
cr Ran mi lowow nigb‘aini;
Jesu, gbo ‗gbe mi
2 mp Ninu ibanuje mi
At‘okan aigbagbo mi
P Em‘olori elese
Gb‘oju mi si O

3 p Ota l‘ode, eru n‘nu,


Ko s‘ire kan lowo mi;
Iwo l‘O ngb‘elese la,
cr Mo sa to O wa

4 Awon iran d‘ese pe,


Won si ir igbala gba;
cr Won gbo ohun anu Re,
Mu mi gbo pelu

5 mp Mo k‘aniyan mi le O,
Mo si ngbadura si O,
Jesu yo mi n‘nu egbe;
Gba mi ki nma ku.

6 cr ‗Gbati wahala ba de,


Nigb‘ agbara idanwo;
Ati lojo ikeyin
Jesu, sunmo mi.
Amin.

838
Ongbe Olprun ngbe okan mi.
OD. 42:2.

1 mp Bi agbonrin ti nmi hele


S‘ipa odo omi,
cr Beni okan mi nmi si O,
Iwo Olorun mi.

2 mp Orungbe Re ngbe okan mi


Olorun alaye:
p Nigba wo ni un o r‘oju Re
Olorun Olanla?

3 p Okan mi o se rewesi?
Gbekele Olorun
cr Eni ti y‘O re ekun re
D‘orin ayo fun o.

4 mp Y‘o ti pe to Olorun mi
Ti un o deni 'gbagbe;
Ta o ma ti mi sihin, sohun
B‘eni ko ni ‘bugbe.
5 mp Okan mi o se rewesi?
cr Gbagbo ‘wo o si ko
f Orin iyin s‘Olorun re;
Orisun emi re.

6 Si Baba, Omo at‘Emi


Olorun ti a nsin
L‘ogo ati ola ye fun
Titi ayeraye.
Amin.

839 6.5.6.5.D.
Mo ti gbadura fun o ki igbagbo re
Ma seye. Lk. 22:32.

1 mp Jesu nigba ‘danwo


Gbadura fun mi;
K‘emi ma ba se O
Ki nsi sako lo,
cr ‘Gba mba s‘iyemeji
KO b‘oju wo mi,
K‘eru tab‘ isaju
Ma mu mi subu.

2 mp B‘aye ba si nfa mi
Pelu adun re,
T‘ohun ‘sura aye
Fe han mi l‘emo,
Jo mu Getsemani
di Was‘iranti mi,
pp Tabi irora Re
L‘oke Kalfari.

3 mp B‘O ba pon mi l‘oju


Ninu ife Re.
Da ibukun Re le
Ori ebo na;
Ki nf ara mi fun O
L‘ori pepe Re:
B‘ara ko ago na,
lgbagbo y‘o mu.

4 p ‗Gba mo ba nre ‗boji


Sinu ekuru;
cr T‘ogo orun si nko
l‘eti bebe na;
mf Un o gbekel‘ oto Re
Ni ‗jakadi ‗ku
Oluwa gb‘emi mi,
S‘iye ailopin
Amin.

840
lfe Tire ni ki a se,
Mat. 26:42.

1 mf Baba mi ‘gba mba nsako lo


Kuro l‘ona Re laye yi,
Ko mi ki nle wi bayi pe:
p ―Se ‘fe Tire.‖

2 mp B‘ipin mi l‘aye ba buru,


Ko mi ki ngba, ki nmase kun;
Ki ngbadura to ko mi, wipe:
p ―Se ‘feTire‖.

3 mp B‘o ku emi nikansoso,


Ti ara on ore ko si;
N‘iteriba un o ma wipe:
―Se ‘feTire.‖

4 mp B‘O fe gba ohun owo mi,


Ohun to se owon fun mi
Uno fi fun O, se Tire ni,
―Se,‘fe Tire.‖

5 Sa fi Emi Re tu mi n‘nu,
Ki On ko si ma ba mi gbe,
Eyit‘o ku, o d‘owo Re,
―Se ‘feTire.‖

6 Tun ‘fe mi se lojojumo


K‘O si mu ohun na kuro
Ti ko je kemi le wipe:
―Se ‘fe Tire.‖

7 p ‘Gba t‘emi mi ba pin l‘aye,


cr N‘ilu to daraju aye
f L‘emi o ma korin na titi
―Se ‘fe Tire.‖
Amin.

841 6.4.6.4.6.4
Alejo ni ile ajeji Eks. 2:22

1 mp Nihin mo j‘alejo
Orin n‘ile;
Atipo ni mo nse,
Orin n‘ile;
Ewu on ‗banuje
Wa yi mi kakiri,
cr Orun ni ilu mi,
orun n‘ile

2 mf B‘iji ba tile nja,


Orun n‘ile;
di Kukuru l‘ajo mi,
Orun n'ile;
Iji lile ti nja,
cr Fe rekoja lo na,
Un o sa dele dandan,
Orun n‘ile.

3 mf L‘odo Olugbala
Orun n‘ile;
cr A o se mi l‘ogo,
Orun n‘ile;
p Nib‘awon mimo wa
L‘ehin ‘rin-ajo won,
Ti won ni ‘simi won,
cr Nibe n‘ile.

4 mf Nje nki o kun n‘tori


Orun n‘ile;
Ohun to wu ki nri,
Orun n‘ile
cr Un o sa duro dandan
L‘otun Oluwa mi:
ff Orun ni ilu mi,
Orun n‘ile.
Amin.

842 8.8.8.
Oluwa mbe fun mi, emi ki yio beru:
kili eniyan le fe si mi? OD. 118:6

i f Un o se foya ojo ibi?


Tabi ki nma beru ota
Jesu papa ni odi mi.

2 Bo ti wu k‘ija gbona to!


Ka mase gbo pe emi nsa;
‗Tori Jesu l‘apata mi

3 p Nko m‘ohun to le de, nko mo


Bi nki yo ti se wa l‘aini
cr Jesu l‘O mo; Y‘O si pese

4 p Bi mo kun f‘ese at‘osi,


cr Mo le sunmo ite-anu
‗Tori Jesu l‘ododo mi

5 p B‘adura mi ko nilari,
cr Sibe ‘reti mi ki o ye;
‘Tori Jesu mbebe loke

6 f Aye at‘esu nde si mi;


ff Sugbon Olorun wa fun mi;
Jesu l‘ohun gbogbo fun mi.
Amin.

843 9.1.9.1. & Ref.


Emi wa pelu yin nigbagbogbo,
Titi o fi de opin aye. Mat. 28:20.

1 Orin kan wa ninu okan mi,


Jesu so jeje wipe;
mp ―Mase beru, mo wa pelu re
Ninu ‘gbi aye gbogbo‖.
f Jesu, Jesu, Jesu,
Ti o dun julo,
Gba gbogbo ife mi,
O si nmu mi korin lo

2 p Ese ti ba ‘gbe aye mi je,


Irora kun okan mi;
mf Jesu ti mu gbogbo re kuro,
O tun ji mi nin‘orun

3 Fun ipese ore-ofe Re


Fun isimi l‘abe Re;
Fun oju rere Re ‘gba gbogbo
f Ni mo se nkorin kikan.

4 Bi mo tile nla omi ko ja,


Ti wahala wa lona;
Ti ona ko si ni igbadun,
On sa wa ni iwaju.

5 f Ni aipe titi, y‘O to mi wa


Lat‘orun giga l‘oke;
Un o fo ba lo si orun mimo,
Un o ma ba joba l‘oke
Amin.

844 8.7.8.7
Awon eni irapada Oluwa yi o pada,
Won o si wa Sioni ti awon ti orin.
Isa 51:11
1 mp Ninu oru Ibanuje
L‘awon egbe ero nrin;
mf Won nkorin ‘reti at‘ayo,
Won nlo sile Ileri.

2 mp Niwajuwa n‘nu okunkun


Ni imole didan ntan;
mf Ara ngba ara won lowo
Won nrin lo li aifoya

3 mf Okan ni imole orun


Ti ntan s‘ara eniyan Re.
Ti nle gbogbo eru jina,
Ti ntan yi ona wa ka

4 Okan ni iro ajo wa,


Okan ni igbagbo wa,
Okan l‘Eni ta gbekele,
Okan ni ireti wa

5 mf Okan l‘orin t‘egberun nko


Bi lati Okan kan wa.
Okan n‘ija, okan l'ewu
Okan ni irin Orun

6 Okan ni inu didun wa,


L‘ebute aini pe kun;
Nibiti Baba wa orun
Y‘Oma joba titi lae

7 cr Nje ka ma nso, eyin ara


T‘awa ti agbelebu,
Ejeka ru, ka si jiya
Tit‘ao fl ri ‘simi

8 f Ajinde nla fere de na,


‘Boji fere si sile;
Gbogbo okun yo tuka
Gbogbo okun yo si tan.
Amin

845 L.M.
Ma ja ogun rere; ma ni igbagbo.
I Tim. 1:18-19.

1 mf Ja ija rere t‘igbagbo,


Ja, nipa agbara Kristi;
Di iye ainipekun mu,
Aye at‘ade re titi.
2 mf Ma saire ije t‘iye,
Gboju soke fun ‘ranwo Re;
cr Kristi li Ona, Iye re,
Kristi li opin ere re.

3 Ma s‘aniyan ohunkohun,
Y‘O pese fun gbogb‘ aini yin
cr Gbekele Krist‘, Amona yin
Eni gbagbo ki yo damu.

4 mf O mbe nitosi, ma beru;


Eni ti ki yi pada ni;
cr Sa gbagbo, si gbeke re le
Y‘O je ohun gbogbo fun o
Amin

846 7.6.7.6.D.
Bi igi opoto ki yio tile tanna,
sugbon emi o mayo ninu Oluwa,
Hab. 3:17-18.

1 mf G ba‘mole yo l‘ojiji
Si Kristian ti nkorin;
Oluwa ni O ndide
Pelu ‘mularada;
Gbati irora ndinku
On a tun fun okan
N‘imole ti ntan sansan
Lati mu l‘araya.

2 cr Pelu isaro didun,


A ranti ife Re;
mf Igbala nla n‘nu Jesu,
Otun ni titi lae;
Eyi le ‘banuje lo,
O nmu okan wa yo,
Ba ko tile mo ola.
A nireti didun.

3 cr Ohun to wu ko mu wa,
On y'O mu wa laja; .
Eni daso bo koko,
Yo da bo eniyan Re,
Labe awosanma Re,
Ko s‘edati ki bo,
Eni mbo awon eye,
Y‘O f‘omo Re l‘onje.

4 cr B‘ajara tab‘opoto
Ko tile so eso,
Bi gbogbo ‘ko tile ro
T‘agbo eran segbe,
mf Olorun mbe bakanna;
f Un o korin iyin Re;
Bi mo ti ngbeke mi le,
Ayo mi yo ma po.
Amin.

847 L.M.
Loto o ti ru ibinuje wa,
O si gbe ikanu wa lo.
Isa. 53:4.

1 cr Gbogbo iya mi n‘Iwo mo,


Iwo t‘a danwo bi emi;
mp Wo ‘kanu mi, wo ‘kanu Re,
Jesu, K‘O ranti Kalfari!

2 O ko ha mo osi eda?
Kristi ha d‘ekun anu se?
p O ko ha mo‘banuje mi,
O ko ha pin n‘nu ‘rora mi?

3 Nko ha ti gbo, nko ha ti mo


Pe, Oluwa ayeraye
T‘orun at‘aye jewo Re
A ma mu ileri Re se?

4 mf Emi mo pe ‘Wo ki o gan


A-ko-bere ‘se igbala;
Mo mo pe Orun ododo
Y‘o la pelu ‘mularada.
Amin

848 8.8.8.D.
Abo mi mbe l‘odo Olorun ti O nse
igbala olotito li aiya. OD. 7:10,

1 cr F‘ona re l‘Oluwa lowo,


Si gbekele l‘ohun gbogbo;
Lojo ibi, iwo yo ri
Pe On nikan l‘O to o gba;
mf Eni gbekele Olorun
Duro sinsin lor‘apata.

2 mf Iwo sa fokan re bale


Si ma duro n‘nu ireti,
F‘itelorun gb‘ohunkohun
T‘ore on ife Re mu wa;
Ma foya, gbogbo aini wa
L‘ Olorun wa mo laiku kan.

3 Mase fi ona Re sile,


Sa ipa re tokan-tokan;
Ma gbekele ileri Re,
Titi gbogbo won yo fi se;
cr Baba ko ko enikan ri
Ti o gbeke l‘E nitoto.
Amin.

849 8.8.8.D.
Mo ti pe o li oruko re; ti emi
ni iwo. Isa. 43:1

1 mf M ase beru ‘wo okan mi;


Eleda mi ni nma foya;
Oluwa pe mi l‘oruko;
O ndabobo, ko si jinna,
Eje Re ti s‘etu fun mi,
O nfe, O si nto mi sibe.

2 cr ‘Gba mo nkoja larin ibu,


Mo fi gbagbo toro ‘ranwo,
Igbi si duro l‘okere,
Won bi kuro li ori mi:
mf Emi ko beru ipa won;
Ko si ewu, Olorun mbe.

3 Mo yio ju igbagbo s‘I,


Mo n tesiwaju larin ‘na;
Ina gbagbe lati jo mi,
Owo ina njo yi mi ka;
MO JEWO agbar'ami na,
Mo ke pe: ―Temi m Jesu‖.

4 cr Olugbala, duro ti mi;


Dabobo mi nigba ‘danwo
Pa mi mo ni ikawo Re,
F‘agbara ‘gbala han n‘nu mi;
Ki apa Re je abo mi,
Ko s‘ohun le ja mi kuro.

5 B‘O si ti pe mi pe ki nwa ‘
WO; Olore, ti ngba ni la,
Un o rin lori okun ti nja,
Igbi yo gbe ese mi ro;
Nki yo beru isan na,
Bi o ti wu ki o le to.
6 mp ‘Gbat‘okunkun b‘oju orun
T‘igbi ‘banuje yi mi ka,
T‘iji ibinu ru soke,
To fere bori okan mi,
mf Emi mi yo ri ‘dake-je,
pp Yo gb‘ohun jejepe, ―simi!‖

7 f Bi mo wa n nu eru‘ponju,
Laisewu un o sete iku;
B‘ese doju ija ko mi,
Ti esu gbe ogun ji mi,
B‘igbo Mose, un o magberu,
Ina ki o pa mi lara.
Amin.

850 15.7.15.7. & Ref.


Nitoriti O ni ife si Mi, nitorina li
Emi O se gba. OD. 91:14

1 cr N‘nu ijakadi aye re a ki yo le segun re,


B‘okan re b‘Oluwa rin;
mf Iwo yo ma segun nso titi iwo yo fi gbade
B‘okan re b‘Oluwa rin
mf B‘okan re b‘Oluwa rin,
B‘okan re b‘Oluwa rin,
IWO ki yo mo ‘subu,
f Sugbon isegun pipe,
B‘okan re b‘Oluwa rin.

2 Awon odo idanwo nla ki yo le bo o mole,


B‘okan re b‘Oluwa rin,
Oko re ki yo ri sinu igbi idamu aye,
B‘okan re b‘Oluwa rin.
mf Itelorun at‘alafia yo tan ‘mole s‘ona re
B‘okan re b‘Oluwa rin;
Igboya ninu idanwo, isegun ninu ija;
Gb‘okan re b‘Oluwa rin.
Amin.

851 8.8.8.6.& Ref.


iya igba isisiyi ko ye latifi se
akawe ogo ti a ofi han ninu wa. Rom. 8:18.

1 mp Eru, aniyan ndamu re,


lsoro nk‘are ba o bi?
mf Onirobinuje, y‘ayo,
Ife Krist‘ to fun o
cr B‘ona su, gbekele ‘fe Re,
Y‘O fi iyin kun okan re,
f Korin ni ‘gbagbo lojojo,
Ife Krist‘ to fun o.

2 mp ‘Wo kuna oro aye bi?


cr Ka si ere; wo Kalfari,
L‘orun ni isura re wa,
Ife Krist‘ to fun o.

3 ‘WO ko gba iyi l‘aye bi?


Sibe, Baba nse ‘toju re,
Fun o li Omo Re se ku,
Ife Krist‘ to fun o.
Amin.

852 10.10.10.7. & Ref.


E wa S‘odo mi gbogbo enyin ti a di eru
wuwo le lori, Emi o fi isimi fun yin.
Mat. 11:28.

1 cr B i eru ese ba nwo O l‘orun,


mf Ore kan mbe to nm‘imi alafia;
T‘O si nmu k‘ailera n‘isegun,
Jesu l‘Oret‘iwo nfe.
mf Jesu l‘Ore t‘iwo n fe (ara mi)
Jesu ni Ore toto (oto)
Fi Jesu s‘ore; si gbeke re l‘E,
N‘tori Jesu l‘Ore toto.

2 Ninu irin ajo re li aye,


On li Ore to le ran o l‘owo;
L‘ayo l‘okan to simi le Jesu.
Jesu l‘Ore t‘iwo nfe.

3 mp ‘Gbati 'danwo ba okan re jagun,


mf Or‘ ofe Re bori gbogbo ibi;
Gbekele Ore ti ko le da O,
Jesu l‘Oret‘iwo nfe.

4 mp ‘Gbati ‘kuku okunkun yi o ka,


Ni igbekele ore-ofe Re;
mf Ore nla yi yo mu imole wa;
Jesu l‘ore t‘iwo nfe
Amin.

853 8.7.10.7.D. & Ref.


Bi igi Opoto ki yio tile tanna, sibe
emi o mayo ninu Olorun igbala mi.
Hab. 3:17 & 18.

1 mf ‘Mole kan mbe leyin ‘kuku,


Gbogb‘egun lo n‘itanna,
Nigbati Oluwa wa nitosi;
Okan wa k‘yo sofo mo;
f ‘Mole ayo Orun kan wa,
Bi ‘mole miran kuna,
Nigbat‘ a mo ife Oba orun,
Ife ti yo bori lae.
ff Aleluya! Aleluya!
O si ti dariji wa,
Aleluya! Aleluya!
Alafia ngbe n‘nu wa,
A layo n‘nu Olugbala,
A si nyo ninu ‘fe Re,
Aleluya! Aleluya!
S‘Oluwa Olubukun.

2 cr ‘Leri Olorun lao fi bo


Ogbun ‘banuje mole;
Oro Re daju, o wa titi lae
mf ‘Reti, ayo lo ntan ka;
A si mo P‘OJO ola yo
Dan ju ‘mole osan lo,
f B‘imole de, okunkun parada!
Beni yo wa titi lae

3 cr Ki ‘mole orun dari wa,


Ka f‘ayo rin l‘ona na,
Ki erin wa je ti ore-ofe,
Fun awon alailera;
Ao wa fun Jesu nikanso
Ayo Re l‘agbara wa,
Tit‘ao fi pade leyin aye yi,
T‘ao ri ewa oju Re
Amin.

854 8.8.8.6. & Ref.


Nitori ti Oun nse itoju n yin
I Pet. 5:7.

1 mf N‘nu gbogbo ‘danwo ti mba mi


Larin idamu aye yi;
cr Iro kan lo nmu ‘nu mi dun
mf Baba ngbero fun mi.
f Baba ngbero fun mi,
Baba ngbero fun mi,
Eese ti un o tun ma beru?
Gbat‘O ngbero fun mi.

2 mp ‘Gbat‘ igbi aniyan ba de


Lati teri okan mi ba;
cr Sibe mo ranti ohun kan
mf Pe: ‘Wo ngbero fun mi.

3 cr Ohunkohun to wu ko de;
Ayo tabi ibanuje,
Ohun kan sa da mi loju
mf Pe: ‘Wo ngbero fun mi.
Amin.

855 14.14.14.10. A Ref.


Beulah nitori inu Oluwa dun si O.
Isa. 62:4.

1 mp Mo n gburo iji ti nja li ona jinjin rere


Mo si mo pe ese ndan ni wo ni aye yi
mf Iye meji at‘eru ko le pami lara mo
Wonyi ko le mu mi kuna Beulah.
f Mo ngbe ni ori oke, gbogbo ‘danwo
si fo lo (yin Krist‘),
Mo nmu n‘ibi orisun ti ko le gbe titi,
Mo nje onje na t‘ise Manna lati oke
orun waa
Nitori mo ngbe nile Beulah.

2 mf Mo jinna s‘ibiti iyemeji ndamu aye,


Nibiti ota ngbogun ti omo eniyan;
Mo ngbe lailewu li ebute oro Olorun,
Ko s‘ewu ‘tori mo ngbe ni Beulali.

3 mf Bo ti wu ki iji le to, eru ko le ba mi,


OWO Olorun li abo to daju fun ini;
Nibe l‘orun nran titi, ko si ifoya tun mi
Ko s‘ewu ‘tori mo ngbe ni Beulah.

4 p ‗Gbati mo now ‗se Olorun okan mi


wariri
cr Mo n gb'ohun ife Re pe On lo nseto
fun mi,
Emi Re nfihan mi pe igbala didun l‘eyi
mf Un o fi ayo gbe ni ile Beulah.
Amin.

856 11.11.11.5
Okan wa duro de Oluwa:
On ni iranlowo 'wa ati asa wa.
OD. 33:20.

1 mf Olorun emi wa at‘igbala wa,


‗Mole okunkun on ‘reti gbogb‘aye,
Gbo, ki O si gba ebe ijo Re yi,
Olodumare.
2 mp Wo bi ibinu ti yi Ijo Re ka,
Wo b‘awon ota Re ti nt‘asia won,
Bi won si ti nju oko oloro won,
‘Wo le pa wa mo.

3 f ‘Wo le ‘ranwo b‘iranwo aye ye,


‘Wo le gba ni low‘ese ti npa ni run,
p Iku at‘esu ko le bor‘ijo Re;
F‘alafia fun wa.

4 Ran wa lowo tit‘ ota o pehinda


Fun won l‘oto Re, k‘a le dariji won
K‘a r‘alafia l‘aye, leyin ija wa;
Alafia l‘orun.
Amin.

857 7.6.7.6 & Ref


A won ti o gbekele Oluwa yio da bi oke
Sion. OD. 125:1.

1 mp Gbekele, Onigbagbo
Bi ‘ja na tile pe,
Iwo ni y‘o sa segun,
Baba y‘o ja fun o
Sa gbekele
B‘okunkun tile su
Sa gbekele
Ile fere mo na

2 mf Gbekele! larin ewu,


‘Danwo nla wa n‘tosi;
Larin wahala aye
Y‘o ma s‘amona re.

3 mf Jesu to lati gba wa,


Ore toto l‘O je;
Gbekele, Onigbagbo!
Sa gbekele d‘opin.
Amin.

858 L.M
Olorun li abo wa ati agbara.
OD. 46:1.

1 mf Olorun l‘abo eni Re,


N‘igba iji iponju de;
K‘awa to se aroye wa,
Sa wo t‘Oun ti iranwo Re.
2 Bi a si oke nla n‘idi,
Ti a ri s‘isale ibu;
T‘isele mi aye papa,
Igbagbo wa ki o yese

3 B‘o ti wu ki ‘gbi na le to,


Ti gbogbo orile-ede
Si nfoya riru omi na
Okan wa mbe l‘alafia.

4 Odo kan wa ti sisan re


Nmu ‘nu ilu Olorun dun;
Iye, ife ati ayo
Nsan larin re, o mb‘omi rin.

5 Odo na li oro iye


Ti nsa koso ipaya wa
‘Leri Re nmu alafia wa
O nfilera f‘okan are

6 Sion ngbadun ‘fe Oba re!


O bo lowo ewukewu,
A ko lori otito Re
Ipile re ko le ye lae.
Amin.

859 8.7.9.7.8.6.10.7. & Ref.


O si ji, O ba afefe na wi. Mk. 4:39.

1 mp Oluwa, iji nja kikan,


Igbi omi nru s‘oke;
Oju orun pelu su dudu,
p ‘Ranlowo ko si n‘tosi;
cr ‘WO ko bere, bi a segbe?
‘WO y‘o ha se le sun
‘Gbati ‘seju kokan d‘eru ba wa
Pe omi n‘iboji wa
mf Afefe at‘igbi y‘oje fe mi;
p Dakeje:
mp Ibase ‘binu riru okun,
Ibase esu tabi ohunkohun,
f Ko si omi t‘ole ri oko na,
ff Ti Oluwu orun at‘aye wa;
cr Won y‘o finu didun se fe mi,
p Dake je, Dake Je
f Won y‘o finu didun se ‘fe Mi
p Dake je.

2 mp Oluwa, pel‘edun emi,


Mo teriba n‘ironu;
pp Inu okan mi ko ni ‗simi,
A! ji k‘Ogbami, mo be;
Igbi ese on binuje
Bo okan mi mole;
cr Mo segbe, Oluwa mi mo segbe
A! yara k‘O si gba mi

3 mf Oluwa, eru ti koju


Idakeje si ti de,
Orun f‘oju han nin‘ ndagun
Orun si wa l‘aya mi;
cr Duro Olurapada mi,
Ma fi mi sile mo;
f Pe l‘ayo, un o d‘ebute ibukun
Un o simi l‘ebute na
Amin.

860 C.M
OluwagbO, Oluwa dariji.
Dan. 9:19.

1 mf Gb‘adura wa, Oba aye


‘Gbat‘ a wole fun O;
f Gbogbo wa nkigbe n‘irele,
di A mbebe fun anu;
Tiwa l‘ebi, Tire l‘anu,
Ma se le wa pada;
Sugbon gbo ‘gbe wa n‘ite Re
Ran ebe wa lowo.

2 p Ese awon baba wa po,


Tiwa ko si kese
Sugbon lati irandiran
L‘o ti f‘ore Re han
Nigba ewu, b‘omi jija
Yi ilu wa yi ka,
IWO l‘a wo, t‘a si ke pe;
K‘a ma ri ‘ranwo Re.

3 p L‘ohun kan gbogbo wa wole


L‘abe ibawi Re;
Gbogbo wa njewo ese wa,
A ngb‘awe fun ‘le wa,
F‘oju anu wo aini wa
Bi a ti nke pe O;
Fi idajo Re ba wa wi,
Da wa si l‘anu re
Amin.

861 1.1.1.5.
Gbo, Oluwa, nigbati mo bafi ohun mi pe:
sanu fun mi. OD. 27:7.

1 cr Olorun, Olor‘-ofe,
‘Gbat‘a nfi ‘rele wa o,
mp Bojuwo ‘le lat‘orun;
‘Gbo, si gbawala.

2 ‘Gba ba pejo n‘ile Re,


T‘a nso ohun t‘o ndun wa,
T‘a nbebe n‘ite anu,
cr Wo wa, gba wa la

3 ‘Gba‘fe Re kun okan wa


Ti a nfe Se ‘feTire,
T‘a nwo oke mimo Re,
cr Baba, gba wa la.

4 mp B‘a ba sako jinna lo,


p T‘ife wa tutu si O,
cr F‘oju anu Re wo wa;
JO dariji wa.

5 mp ‘Gbati ‘banuje ba de
Pelu idamu aye,
cr F‘alafia f‘okan wa;
Jesu, gba wa la.

6 cr Ohun wu k‘edun wa je,


‘Gbat‘ a ngbadura si O,
F‘opin si ipaya wa;
Gbo, si gba wa la.
Amin.

862 C.M.
Dide, Oluwa, Olorun gbe owo Re soke:
mase gbagbe oluponju: OD. 10:12.

1 cr Olorun, ‘ranwo eni Re;


‘Reti wa n‘igba ‘bi,
A gba ‘WO Eni Airi gbo,
mp Awa nwa O sibe

2 cr Ese ti awon elese


Nfojudi ipa Re,
di Ti won si nhale b‘enipe
‘WO ko ri ese won?

3 Oluwa, dide k‘o gba wa;


A m‘oran wa t‘o wa,
F‘ododo at‘ipa j‘oba,
‘WO nikan li Oba.

4 mf IWO mo gbogbo ife wa;


‘Ranwo Re wa n‘tosi
Pese okan wa fadura,
Si gba adura wa;
Amin.
863 6.6.6.6. & Ref.
Iranlowo wa mbe li oruko Oluwa ti O da
Orun on aye. OD. 124:8.

1 mf Baba,‘Wol‘ato wa
F‘anu at‘or‘-ofe;
JOWO gbo igbe wa,
Mam‘oju Re kuro!
cr Baba, na ‘wo agbara Re,
Ki o si bukun ile wa.

2 f Dide, Oluwa wa,


JOWO foruko Re;
Le gbogbo ese lo
Kuro ni ile wa.

3 RO ojo ‘bukun Re
Siwa lopolopo;
K‘a le ma gbe O ga,
K‘a ma yin O titi.

4 Fi ogbon Re orun
F‘awon olori wa;
Se won ni iran se Re
Ki won fe ododo.

5 mf Ru ijo Re soke
Pelu ina ife;
Tun dapo si okan,
F‘oto at‘iye fun.

6 cr Fi ore-ofe Re
F‘awon alufa Re;
Se won l‘ojise Re
Ninu iwa-mimo.

7 cr Je k‘a fe ile Re,


K‘a ya ‘jo Re soto,
K‘a mu eje wa wa
Lati josin fun O.

8 mf F‘alafia fun wa;


Le ota wa jinna,
K‘a ma f‘afojudi
Dese s‘ola-nla Re.

9 B‘a ti l‘agidi to,


Sibe Tire ni wa
Ko s‘Olorun miran
Ti ao sin lehin re.
Amin.

864 11.11.7.7.11.4.
Oluwa Olorun wa Olodumare njoba.
Ifi. 19:6.

1 mf Iwo okan t‘eru npa, ―Jesu njoba‖;


Woke, n‘omije re nu, ―Jesu njoba‖;
B‘ogun ota tile po,
Won ki yio le bori;
Gbekele Jesu ki y‘o ko o sile,
f ―Jesu njoba‖.

2 f K‘okiki otito na, ―Jesu njoba‖;


Eyin mimo, gberin na, ―Jesu njoba‖ Sion, ji! ojumo mo,
Wo bo ti la lohun ni;
Goro l‘oluso nke pe: ―Jesu njoba‖;
―Jesu njoba‖

3 f Ji, Ijo Kristi l‘aye, ―Jesu njoba‖;


Gbe ‘hamora gboya wo, ―Jesu njoba
Laipe on y‘osokale
Lati gba o ni Tire;
A o si gbe ese mi, ―Jesu njoba‘
―Jesu njoba‘.
Amin.

865 C.M.
Jakobu yio ha sele dide?
Amo. 7:2.

1 mf ―Tani o gbe Jakob‘ dide?‖


Ore Jakob‘ ko po;
Eyi t‘o je ‗yanu ni pe,
Imo won ko sokan.

2 mf ―Tani o gbe Jakob‘ dide?‖


Ota Jakob‘ n‘ipa:
f Mo r‘ayo ‘segun l‘oju won,
p Won ni, ―o pari fun‖.

3 mf ―Tani o gbe Jakob‘ dide?‖


A ha r‘eni le wi?
p Eka t‘o ro nibule yi,
cr O ha tun le ye mo?

4 mf Oluwa mi, ise Re ni!


Ko s‘eni t‘o le se:
p Se b‘iri s‘ori Jakobu,
f On yio si tun ye.
Amin.

866 8.8.8.8.D.
Nibo ni iwo wa?
Gen. 3:9.

1 mf Nigbat‘ idanwo yi mi ka,


p Ti idamu aye yi mi ka;
T‘ota fara han bi ore
Lati wa iparun fun mi;
f Oluwa jo, ma s‘aipe mi
Bo ti pe Adam nin‘ogba di Pe,
―Nibo lo wa‖ elese
Ki nle bo ninu ebi na.

2 f Nigbat‘ Esu n‘nu ‘tanje re


Gbe mi gori oke aye,
T‘o ni ki nteriba fun on
K‘ohun aye le je temi

3 f Gbat‘ ogo aye ba fe fi


Tulasi mu mi rufin Re
T‘o duro gangan lehin mi:
Ni ileri pe ko si nkan

4 Nigbati igbekele mi
Di t‘ogun ati t‘orisa
T‘o gede di adura mi
Ti ofo di ajisa mi

5 Nigbati mo fe lati rin


L‘adamo at‘ife ‘nu mi
T‘okan mi nse hilahilo,
Ti nko gbona ti nko tutu

6 p N‘igba mo sonu bi aja


Lai gbo ifere ode mo,
Ti nko nireti ipada.
Ti mo npa fo ninu ese

7 Nigbati ko s‘alabaro;
Ti Olutunu si jina;
p T‘ibanuje, b‘iji lile
cr Te ori mi ba n‘ironu.
Amin.

867 8.7.8.7.
Wa Sodo mi.
Isa. 55:3.

1 mf E mi o lo s‘odo Jesu,
Eni npe mi pe ki‘m wa,
Eni t‘O se Olugbala
Fun elese bi emi.

2 mf Emi o lo sodo Jesu,


mp Irira at‘ibinu,
cr Ika at‘ise t‘o buru,
T‘eyan nse, On ko ni.

3 mf Emi o lo sodo Jesu,


O dun mo mi ki nse be;
Tal‘ o femi bi ti Jesu,
Eni ti O gba ni la?

4 Emi o lo sodo Jesu,


Jesu t‘o se Ore wa:
Anu wa ninu Re pupo,
Fun elese bi emi.
Amin.

868 C.M.
Mase je ki awon ti nwa O ki o
damu. OD. 69:6.

1 mf Wo bi awa eniyan Re
p Ti wole l‘ese Re;
Olorun! kiki anu Re
Ni igbekele wa.

2 f Idajo t‘o banileru,


Nfi agbara Re han;
Sibe, anu da lu wa si,
Awa si ngbadura.

3 mf Olorun, ose da wa si,


Awa alaimore?
Jo, je k‘agbo ikilo Re,
Nigbati anu wa.

4 Iwa buburu ti po to,


Yika ile wa yi!
‘Bukun ile wa lo to yi!
Wo b‘o ti buru to.

5 f Oluwa, fi ore ofe


Yi wa l‘okan pada!
Ki a le gba oro Re gbe,
K‘a si wa oju Re.
Amin.

869 L.M.& Ref.


Eni ti o si gbekele Oluwa, ibukun nifun.
Owe 16:20.

1 f Ojo nla l‘ojo ti mo yan


Olugbala l‘Olorun mi;
O ye ki okan mi ma yo,
K‘o si ro ihin na kale
f Ojo nla l‘ojo na
p Ti Jesu we ese mi nu;
O ko mi ki nma gbadura
Ki nma sora, ki nsi ma yo,
Ojo nla l‘ojo na
Ti Jesu we ese mi nu.

2 mf Ise igbala pari na,


Mo di t‘Oluwa mi loni;
On l‘o pe mi, ti mo si je,
ff Mo f‘ayo j‘ipe mimo na.

3 Eje mimo yi ni mo je
F‘eni to ye lati feran:
Je k‘orin didun kun ‗le RE
Nigba mo ba nlo sin nibe

4 Simi, aiduro okan mi,


Simi le Jesu Oluwa;
Tani je wipe aye dun,
Ju odo awon angeli?

5 ‘Wp orun t o ngbo eje mi,


Y‘o ma tun gbo lojojump,
p Tit‘ ojo t‘emi mi y‘o pin
Ni un o ma m‘eje mi na se
Amin.

870 8.7.8.7.7. & Rcl‘.


Nitoriti ko si aini fun awon ti o
beru Re. OD. 34:9.

1 mp Oro aye le di ‗baje


Ohun ti mo fe le bo,
cr Itura mbe l‘odo Jesu,
Ki l‘ohun ti mo tun nfe?
Ki l‘ohun ti mo tun nfe?
mf Mo ni Krist‘ ko s‘aini
Owo Re ntu ebun ka
Un o ma korin yin titi
Mo ni Krist‘ ko s‘aini mo.

2 mp Bi ayo aye ba kuna,


Lati mu inu mi dun,
mf Jesu ti ru ‘banuje mi,
N‘nu Re mo r‘ohun gbogbo,
N‘nu Re mo r‘ohun gbogbo.

3 mf Sinu ibu ibukun Re,


Jesu si ‘lekun sile,
f Ninu Re mo l‘ohun gbogbo,
Aini ko si fun mi mo,
Aini ko si fun mi mo.
Amin.

871 7.6.7.6.7.6.D.
Olorun ayeraye ni ibugbe Re
Deut, 33:27.

1 mp Laifoya l‘apa Jesu,


Laifoya l‘aya Re;
cr Labe ojij‘ife Re
L‘okan mi o simi
p Gbo! ohun angeli ni,
Orin won d‘eti mi
cr Lati papa ogo wa,
Lati okun Jaspa;
mf L‘aifoya l‘apa Jesu,
L‘aifoya l‘aya Re,
L‘abe ojij‘ ife Re
L‘okan mi o simi.

2 mp L‘aifoya l‘apa Jesu,


Mo bo lOW‘ aniyan;
Mo bo lowo idanwo,
Ese ko nipa mo;
Mo bo lowo ‘banuje,
Mo bo lowo eru;
cr O ku idanwo die,
O k‘omije die,
mf Laifoya l‘apa Jesu
Laifoya l‘aya Re
L‘abe ojij‘ ife Re
L‘okan mi o simi.

3 mp Jesu, abo okan mi,


Jesu ti ku fun mi;
f Apata ayeraye
L‘emi o gbekele;
Nihin l‘emi o duro
mp Tit‘oruy‘o koja;
cr Titi un o fi ri ‘mole
Ni ebute ogo.
mf Laifoya l‘apa Jesu,
Laifoya l‘aya Re,
L‘abe ojij‘ ife Re
L‘okan mi Osimi.
Amin

872 S.M
Oluwa, IWO ni mo gbeke mi le.
OD. 31:1.

1 mf Mo f‘emi mi s‘abe
Itoju Re, Jesu;
IWO ki y‘o ko mi sile,
‘WO l‘Olorun ife.

2 F ‘WO ni mo gbekele,
‘WO ni mo f‘ara ti;
Rere at‘otito ni O,
Eyi t‘O se lo to.

3 Ohun t‘o wu ko de,


Ife Re ni nwon n se;
p Mo f‘ori pamo s‘aya Re,
Nko foya iji yi.

4 f B‘ibi tab‘irede,
Y‘o sadara fun mi;
Ki nsa ni Ol‘ohun gbogbo
Ohun gbogbo n‘nu Re.
Amin.

873 C.M.
Oruko Re dabi ikunra ti a tu jade.
O. Sol. 1:3.

1 f B‘oruko Jesu ti dun to


L‘eti onigbagbo;
O tan ‘banuje on ogbe,
O le eru re lo.
2 mf O wo okan t‘o gb‘ogbe, san,
O mu aya bale;
Manna ni fun okan ebi,
Isimi f‘alare.

3 f Apata ti mo kole le,


Ibi isadi mi
Ile isura mi t‘o kun
F‘opo ore-ofe

4 cr Jesu, oko mi, ore mi,


Woli mi, Oba mi,
Alufa mi, Oba iye,
Gba orin iyin mi.

5 p Ailera f‘agbara 'nu mi;


Tutu si l‘ero mi,
'Gba mo ba ri O b‘O ti ri,
Un o yin O b‘o ti ye.

6 f Tit‘igba na, ni ohun mi


di Y‘o ma royin ‘ fe Re;
di Nigba iku k‘oruko Re
p F‘itura fokan mi.
Amin.

874 13.11.13.11.13.11.14.11.& Rcl


Emi ni itanna lili awon afonifoji.
O. Sol. 2:1.

1 mf Mo ti ni Jesu l‘ore,
O j‘ohun gbogbo fun mi;
On nikan l‘Arewa ti okan mi fe,
On n‘itanna ipado, On ni Enikan na
T‘O le we mi nu kuro n‘nu ese mi
cr Olutunu mi l‘O je n‘nu gbogbo wahala
On ni ki n k‘aniyan mi l‘Oun lori,
f On ni Itanna Ipado, Irawp owuro,
On nikan l‘Arewa ti okan mi fe
cr Olutunu mi l‘O je, n‘nu gbogbo wahala
On ni ki nk‘aniyan mi l‘On lori;
f On ni Itanna ipado, Irawo owuro,
On nikan l‘Arewa ti okan mi fe.

2 cr O gbe gbogbo ‘banuje at‘irora mi ru,


O j‘odi agbara mi n‘igba ‘danwo;
‘Tori Re mo k‘ohun gbogbo ti mo ti fe
sile,
O si f agbara Re gbe okan mi ro;
mp Bi aye tile ko mi, ti Satani dan mi wo,
Jesu yo mu mi d‘opin irin mi;
mf On ni itanna ipado, irawo owuro,
On nikan l‘Arewa ti okan mi fe.

3 mf On ki y‘o fi mi sile, be k‘y‘o ko mi nihin,


Niwon ti nba fi ‘gbagbo p‘afin Re mo;
Oj‘odi ‘na yi ma ka, n ki y‘o berukeru,
Y‘o fi manna Re b‘okan mi t‘ebi npa, ‘Gba mba d‘ade n‘ikeyin, un o r‘oju
‗bukun Re,
Ti adun Re y‘o ma san titi lae,
f On ni Itanna Ipado, irawo owuro,
On nikan l‘Arewa ti okan mi fe
Amin.

875 10.8.10.8. & Ref.


E wa sodo mi, gbogbo enyin ti n sise,
ti a si di eru wiwo le lori, Emi o sifi
isimi fun nyin. Mat. 11:28.

1 mp B ‘eru ese re ba nwo o lorun,


Pe Jesu wole okan re;
B‘o nd‘aniyan isoji okan re,
mf Pe Jesu wole okan re,
cr Le ‘yemeji re sonu,
Ba Oluwa re laja;
di Si okan re paya fun,
Pe Jesu wole okan re.

2 mf Bi o ba nwa iwenumo kiri,


Pe Jesu wole okan re;
Omi ‘wenumo ko jina si o,
Pe Jesu wole okan re.

3 p B‘igbi wahala ba ngba o kiri


Pe Jesu wole okan re;
cr B‘afo ba wa ti aye ko le di,
Pe Jesu wole okan re

4 p Bi ore t‘o gbekele ba da o


Pe Jesu wole okan re;
mf On nikan ni Olubanidaro,
Pe Jesu wole okan re,

5 mf B‘o nfe korin awon olubukun


Pe Jesu wole okan re,
Bi o nfe wo agbala isimi,
Pe Jesu wole okan re.
f ‘Yemeji mi ti fo lo,
Mo b‘Olorun mi laja,
Mo s‘okan mi paya fun,
Jesu ti wole okan mi.
Amin.

876 8.8.8.6.
Emi ni, ma beru. Gen. 26:24.

1 mf N ‘irumi at‘iji aye,


Mo gbo ohun itunu kan;
di O nso simi l‘eti wipe:
cr ―Emi ni, mase beru‖

2 mp Emi l‘o we okan re mo,


Emi l‘o mu ki o riran;
cr Emi n‘iye imole re,
―Emi ni; mase beru‖

3 mf Awon igbi omi wonyi


Ti f‘agbara won lu mi ri,
Won ko le se o nibi mo;
― Emi ni; mase beru‖

4 p Mo ti mu ago yi l‘ekan,
‘Wo ko le mo kikoro re;
Emi ti mo bi o ti ri
―Emi ni; mase beru‖.

5 mf Mo pe lor‘eni arun re
Oju mi ko ye lara re;
cr Ibukun mi wa l‘ori re;
―Emi ni; mase beru‖.

6 mf ‘Gbat‘ emi re ba pin laye


T‘awon t‘orun wa pade re;
‘Wo o gbohun kan to mo, pe:
―Emi ni;mase beru‖.
Amin

877 S.M.
Ma beru, nitori Emi wa pelu re.
Gen. 26:24.

1 f F‘eru re f‘afefe;
N‘ireti, ma foya;
p Olprun gbo ‘mikanle re;
Y‘o gbe ori re ga.

2 N‘irumi at‘iji,
Y‘o s‘ona re fefe;
Duro de igba Re; oru
Y‘o pin s'ojo ayo.
3 p Okan re ha wuwo?
O re emi re bi?
f Gbon gbogbo ifoya kuro,
Le gbogbo eru lo.

4 mf B‘o ko tile kuro,


Sibe orun, aye
Nso p‘Olorun wa lori ‘te,
O njoba lododo!

5 Fi yiyan on sise
Le ase re lowo;
‘Wo y‘o si f‘iyanu jewo
Ogbon at‘ipa Re

6 Y‘o han pe imo Re


Gaju ero re lo
‘Gbat‘ On ba yori ise na
Ti nfo o li aya;

7 cr IWO r‘ailera wa,


O si mo ero wa;
di Gbe owo t‘are mu s‘oke,
M‘ekun ailera le!

8 N‘nu iye tab‘iku,


K‘a kede oto Re,
K‘aso t‘ife o n ‘toju Re
Tit‘ opin emi wa.
Amin.

878 D.C.M.
Bi enikeni ba wa ninu Kristi,
O di eda titun. II Kor. 5:17.

1 mf Ewa ‘tanna ooro kutu,


‘Mole Osan gangan,
Pipon orun ni ojoro
di Won ti yara sa to!
cr A nfe enu ‘bode orun,
Ita wura didan
Awa nfe Orun ododo,
Ti ki wo titi lae.

2 B‘ ireti giga wa l‘aye


Si ntete saki to;
Abawon melomelo ni
N b‘agbada Kristian je?
A fe okan ti ki d‘ese
Okan ti a we mo,
Ohun lati yin Oba wa
L‘osan, l‘oru titi

3 Nihin ‘gbagbo pe ‘reti mbe


Lati to wa soke
Lohun pipe alafia.
Ju b‘a ti le fe lo
Nipa ife on ‘rora Re,
Nitori iku Re.
Ma je k‘a subu l‘ona Re
K‘a so ade wa nu.
Amin.

879 6.6.8.6.8.8.
E gba ajaga mi si orun nyin, enyin o si
ni isimi fun okan nyin
Mat. 11:29.

1 cr Mo simi le Jesu
‘Wo ni mo gbekele;
p Mo kun fun ese at'oji
Tani mba tun lo lo?
Li okan aya Re nikan
L‘okan are mi simi le.

2 mf Iwo Eni mimo!


Baba simi n‘nu Re,
Eje etutu ti O ta
Lo si mbebe fun mi;
cr Egun tan, mo d‘alubukun;
Mo simi ninu Baba mi.

3 mf Eru ese mi ni,


‘Wo l‘o da mi n‘ide;
cr Okan mi si fe lati gba
Ajaga Re s‘orun;
f Ife Re t‘o gba aya mi
So ise on lala d‘ayo.

4 ff Ojo ologo na,


Isimi orun mbe
di Ese at‘iroray‘o tan,
Emi o si dele;
mf Un o jogun ile ileri,
Okan mi o simi laelae.
Amin.

880 D.C.M.
IWO ni ibi ipamo.
OD. 32:7.

1 mf Jesu,‘Wo n‘ibi ;sadi mi,


‘Wo ni mo gbekele;
Oro Re n‘iranlowo mi
cr Emi alailera,
Nko ni ejo lati ro
Ko s‘ohun ti un o wi;
f Eyi to pe, Jesu mi ku,
Jesu mi ku fun mi.

2 mp Igba iji‘danwo ba nja,


T'ota ndoju ko mi
mf Ite anu n‘isadi mi,
Nibe n‘ireti mi;
Okan mi yio sa t‘O wa
‘Gba‘banuje ba de;
f Ayo okan mi l‘eyi pe,
Jesu mi ku fun mi.

3 mp Larin iyonu t‘o wuwo


T‘eniyan ko le gba;
Larin ibanuje okan
Ati ‘rora ara,
cr Ki lole fun mi n‘isimi
Ati suru b‘eyi?
T‘o ns‘eleri l‘okan mi pe
f Jesu mi ku fun mi.
Amin.

881 10.10.10.8. & Ref.


Awon eni irapada Oluwa .......
nwon o ri ayo ati inu didun gba.
Isa. 35:10.

1 mf Bi iwo nfe ri idariji gba,


Alafia ti nle ‗banuje lo;
Woke sodo Jesu t‘o ku fun o
Lati ra igbala kikun
cr Wa si abe agbelebu Re,
ka isura aye yi sofo
di We nin‘ eje t‘o nsan lat‘ oke
mf Gba igbala re ni kikun

2 mf Bi o nfe ki o joba l‘okan re


We ninu isun si gba iwosan
di Wa we ninu eje Odagutan
Gba igbala re ni kikun

3 mf Bi o nfe ni igboya lati ja


Ma rin n‘nu mole at‘iwa mimo;
Lati ma sin ni omnira okan,
Gba igbala re ni kikun

4 mf Ro m‘agbelebu fun iwa-mimo


Ka oro aye yi s‘ohun asan;
di Wole lese Re, yio we o mo,
Gba igbala re ni kikun.
Amin.

882 8.7.8.7.D.
Bi iwo ba gbagbo, iwo o ri ogo Olorun.
Jn. 11:40.

1 B‘o ti dun lati gba Jesu


di Gbo gegebi oro Re;
K‘a simi lor‘ileri Re,
mf Sa gbagbo l‘Oluwa wi
f Jesu, Jesu, emi gbagbo,
Mo gbekele n‘gba gbogbo,
Jesu, Jesu, Alabukun
Ki nle gbekele O si.

2 mf B‘o ti dun lati gba Jesu,


K‘a gb‘eje ‘wenumo Re
Igbagbo ni ki a fi bo
Sin ‘eje wenumo na.

3 mf B‘o ti dun lati gba Jesu,


Ki nk‘ara ese sile,
Ki ngb‘ayo, iye, isimi
Lati odo Jesu mi.

4 f Mo yo mo gbeke mi le O,
Jesu mi, Alabukun;
Mo mo pe O wa pelu mi,
Ntoju mi titi dopin.
Amin.

883 5.5.11.D
Tire sa ni gbogbo ohun ti ise temi.
Jn. 17:10.

1 mf T‘Olorun l‘emi
‘Tunu nla l‘eyi;
Ibukun nla ni pe temi ni Jesu
Mo layo pupo
N‘nu Od‘agutan
f Ire oko Re si nmu okan mi yo
2 mf Iro ayo na
Ni adun oto;
Eni ba si ti ri paradise
K‘a mo Jesu mi
Ati eje Re
Iye ailopin ni, orun ni laye.

3 Mo sure tete
Lo s‘ase t‘orun;
T‘ohun je ekun re t‘ihinjetowo
Un o mo ‘yi daju
‘Gba mba f‘ayo lo
S‘orun t‘o ga julo, n‘nu ife Jesu.
Amin.

884 8.6.8.6.8.8.8.3.
Oluwa li apata mi, ati ilu olodi mi
ati Olugbala mi. OD. 18:2.

1 mf Jesu j‘ohun gbogbo fun mi,


Ayo at‘aye mi;
On l‘agbara mi n‘gbakugba
Laisi Re, un o subu
N‘gba ‘banuje mo sa t‘o lo
cr N‘gba danwo, O mu‘nu mi dun
Ko s‘eni to dabi Jesu;
f Ore mi

2 mf Jesu, j‘ohun gbogbo fun mi,


Ore mi n‘gba danwo,
Mo lo sodo Re fun ‘bukun
Mo ri ‘gba ni kikun;
O ran orun ati ojo,
At‘eso to pon fun ‘kore,
At‘opolopo ibukun;
f Ore mi.

3 mf Jesu j‘ohun gbogbo fun mi


Un o sa j‘oloto s‘l
Un o se ore nlanla yi
T‘o s‘oloto si mi
Mo yege bi mo ba tele
O npa mi mo l‘osan, loru;
Em‘o tele l‘osan, loru
f Ore mi.

4 mf Jesu j‘ohun gbogbo fun mi,


Un ko fe ore miran
Mo gbekele nisisiyi
Ati titi d‘opin;
Igbesi aye alafia
Ti ko l‘opin pel‘Ore yi
Ni y‘o je ipin mi titi;
f Ore mi.
Amin.

885 7.6.7.6. & Ref.


E ma rin nipa ti emi, enyin ki yio
si mu ifekufe ti ara se.
Gal. 5:16.

1 ‗Gbati mo ti gba Jesu,


Iyebiye lo je;
f Ayemi wadi otun,
O si dabi orun,
Aye dabi orun,
Aye dabi orun,
(Aye dabi orun nihin)
Gbati ‘fe oruko
cr Jesu ba wonu okan eniyan,
Aye dabi orun,
Gbati Jesu ngbe lokun mi
Aye dabi orun.

2 Un ko n‘idalebi lokun
Sugbon ayo orun;
cr Mo fara mi f‘Oluwa
Fun ‘segun lor‘ese

3 Mo nrin lona toro ni


T‘ibinu je ‘rira;
Ife orun at‘ayo –
Si kun ‘nu okan mi

4 mf Un ko gbe aye s‘okan,


Iberu ko si mo;
Adun aye ko le fa mi,
Mo ni orun nihin.
Amin.

886 7.7.6.D. & Ref.


Kristi ti ra wa pada.
Gal. 1:1.1

1 f Ayo wa n‘nu okan mi,


Eyi t‘enu ko le so,
Gba Jesu njoba n'be
O le gbogbo ese lo,
O m‘ojo ‘rapada wa
Gba Jesu njoba n‘be,
ff Gba Jesu njoba n‘be) 2x
Alafia kun okan mi
At'ayo ti ko lopin,
Gba Jesu njoba n‘be.

2 f Ayo at 'alafia de
Ti y'o ma po titi lae
Gba Jesu njoba n‘be
Ibukun nduro de mi
Ati ‘segun t‘ologo
Gba Jesu njoba n‘be.

3 f Ko je femi nikan ‘le,


Gba mo je Tire nikan,
cr Gba Jesu njoba n‘be;
O si nmu okan mi yo;
mf Mo fi gbagbo gbohun Re,
Gba Jesu njoba n‘be.

4 cr Orun wa n‘nu okan mi


B‘igbi tile yi mi ka,
Gba Jesu njoba n‘be
Bi mo ti ntesiwaju
L‘ona t‘awon mimo nrin
Gba Jesu njoba n‘be.
Amin.

887 8.8.8.D.
Bi iwo ba le gbagbo, ohun gbogbo ni sise
fun eni ti o ba gbagbo Mk. 9:23.

1 mf Ohun gbogbo lo je sise


F‘eni t‘o ba gba Jesu gbo;
Oruko Re un ko kegan mo,
Otito Re ni mo di mu,
cr Mo gbagbo pe ohun gbogbo
Ni sise fun mi ninu Krist ‘.

2 cr O di aigbodo mase pe
Ki ese parun ninu mi,
Emi mo pe be ni yo ri,
mf Mo gbeke l‘ododo Jesu,
B‘iwo ba le s‘ohun gbogbo
Emi na le se ninu Re.

3 mf B‘aye ba kegan oro na,


Oro Olorun ko le ye,
Iwo nfo agbara ese,
O daju pe Iwo le se
Ko sohun to soro fun O,
Sise l‘ohun gbogbo n‘nu Re.

4 mf Sise l‘ohun gbogbo fun O,


Fun Krist‘ agbara Olorun,
Fun mi ‘gbati mo d‘atunbi
Ti mo si di eda titun,
Ese ko le bori mi mo,
Sise l‘ohun gbogbo fun mi.

5 mf Sise l‘ohun gbogbo fun O.


Fun Krist‘ agbara ninu mi;
Tan ogo imole Re ka,
Ki nma wa fun ara mi mo,
Ki nfihan lat‘isisiyi,
Adun agbara ife Re
Amin.

888 8.7.8.7.
Emi ni Oluso agutan rere.
Jn. 10:11

1 cr A le ri Olus‘agutan
To feran wa bi Jesu,
Olugbala wa ti O nfe
Ka ma pejo l‘ese Re

2 mf Ese ti eyin fi nfonka


B‘agbo-eran t‘eru mba
mp Eyin ope, e se nsako
Kuro labe ife Re.

3 mf Anu Olorun ti po to!


O po bi omi okun;
Ododo Re kun fun ore
To po ju omiran lo.

4 Ko si ibi ti a nkedun
F‘araye ju t‘orun lo;
cr Nibe li a nfoju anu
Wo gbogb‘ asise eda.

5 mf Idariji mbe f‘elese


Or‘-ofe mbe f‘eni re;
Anu mbe lod‘ Olugbala;
Iwosan mbe n‘n‘eje Re

6 f Idande mbe lopolopo


N‘nu eje ta ta sile;
Ayo mbe fun gbogbo aye
N‘nu iya Olori wa.
7 N‘tor‘ ife Olorun gboro
Ju oye eniyan lo;
Ife Baba, Eni Aiku,
Je ife‘yanu pupo.

8 Bi ife tiwa l‘ailetan,


di A ba gbe okan wa le;
Aye wa iba kun fayo
Ninu ife Oluwa.
Amin.

889 L.M.
Ese ti enyin fi se ojo be,
enyin onigbagbo kekere?
Mat. 8:26.

1 mp Sa dake okan mi,


Oluwa re wa mbe;
Eni t‘O ti se ileri,
Yi o fe mu u se

2 mf On ti fa o lowo,
O mu o de ‘hinyi;
Y‘o pa o mo la ewu ja,
Tit‘ opin aye re.

3 Nigba t‘iwo ti bo
Sinu wahala ri,
Igbe re na ki On ha gbo,
T‘o si yo o kuro?

4 B‘ona ko tile dan,


Yio mu o de ‘le;
f Sa ti wahala aye tan
O san fun gbogbo re.
Amin.

890 10.9.10.9 & Ref


Jesu so fun won pe.........Emi wa pelu yin
Nigba gbogbo, titi o fide opin aye.
Mat. 28:20.

1 mf Ore bi Jesu kosi laye yi,


Oun nikan l‘ore otito,
Ore aye yi y‘o fi wa sile;
Sugbpn Jesu ko je gbagbe wa.
Ah! ko je gbagbe wa; 2ce
Sugbpn Jesu ko je gbagbe wa.
2 Akoko nkoja lo lai f‘ota pe;
A fojo kan sunmole wa si;
Onidajo mbo, gongo yio so;
Awawi kan kosi l‘ojo na.

3 Duro d‘Oluwa, ma siyemeji


Ohunkohun t‘o wu ko le de;
‘Gbat‘ o ro p‘o pin ‘ranwo Re y‘o de;
Eni ‘yanu l‘Oba Oluwa.
Amin

891 C.M
Bikose a tun eniyan bi,
on kole ri ijoba Olorun.
Jn. 3:3.

1 f Okan mi bale, mo soji


N‘gbati mo mo Jesu;
Gbogbo ese mi l‘O fi ji;
Ogo f‘Atobiju

2 mf L‘ojo kan l‘awa y‘o d‘orun:


Wahala y‘o d‘opin
Ibanuje ko ni si mo;
Ayo y‘o je tiwa.

3 f Gbogbo aye ba je temi,


Asan ni eyi je;
Oro ti kole dibaje
L‘o mbe fun mi loke.
Amin.

892 8.7.8.7.8.7.
Ki oju Re le si si ile yi li
osan ati li oru.
I A. Oba 8:29.

1 mf Kristi n‘ipile t‘o daju.


Krist‘ l‘Ori at‘lgunle
Asayan at‘Iyebiye,
O so gbogbo Ijo lu;
Iranwo Sioni Mimo,
Igbekele Re titi.

2 mp Si tempili yi l‘an pe O,
JO, wa loni, Oluwa;
Ni opo inu rere Re;
Gbo ebe eniyan Re;
Ma da ekun ibukun Re
Sinu ile yi titi.
3 Fun awon omo Re l‘ebun
Ti won ba toro nihin
Ore ti won ba si ri gba
Ko ma je ti won titi;
Nikeyin, ninu ogo Re
Ki won ma ba O joba.

4 ff Ogo at‘ola fun Baba,


Ogo at‘ola f‘Omo,
Ogo at‘ola fun Emi,
Metalokan titi lae.
At‘ayeraye, Okanna.
Bakanna titi aye
Amin.

893 6.6.6.6.8.8.
Ibukun ni fun awon ti ngbe inu ile R.
OD. 84:4.

1 mf Kristi n‘ipile wa,


Lori Re lao kole,
Awon mimo nikan
L‘o ngb‘ agbala orun
Ireti wa
T‘ore aye,
T‘ayo ti mbo
Wa n‘nu ‘fe Re

2 f Agbala mimo yi
Yo ho f‘orin iyin;
A o korin iyin s‘l
Metalokan mimo,
Be lao f‘orin
Ayo kede
Oruko Re
Titi aye.

3 mf Olorun Olore,
F‘iyesimi nihin:
Gba eje t‘a mu wa
At‘ebe wa gbogbo;
K‘O si f‘opo
‘Bukun dahun
Adura wa
Nigba gbogbo.

4 cr Nihin je k‘ore Re
T‘a ntoro lat‘ orun
Bo s‘ori wa lekan
Ko ma si tun lo mo
di Tit‘ojona
T‘ao s‘akojo
p Awon mimo
Sib‘isimi.
Amin.

894 L.M
Ki oju Re le fi si ile yi li
osan ati li oru.
I A.Oba 8:29.

1 mf Afi ipile yi lele


Ni oruko Re Oluwa
Awa mbe O Oluwa wa
Ma toju ibi mimo yi.

2 ‘Gba eniyan Re ba nwa O;


T‘elese nwa O n‘ile yi,
Gbo, Olorun lat‘ orun wa
F‘ese won ji won, Olorun.

3 Gba t‘awon ‘ranse Re nihin


Ba nwasu ‘hinrere Kristi;
Sibe jeki ‘se ‘yanu nla
Ma se nipa oruko Re

4 f ‘Gb‘ awon omode ba si nko


Hosana si Kristi Oba won
K‘angeli ba won ko pelu,
K‘orun at‘aye jo gberin.

5 f Jehofa O ha ba ni gbe
Ni aye buburu wa yi?
Jesu O ha je Oba Wa?
K‘Emi Mimo si ma gbe hin?

6 f Ma je ki ogo Re kuro
Ninu ile ti a nko yi;
Se ‘joba Re ni okan wa,
Si te ite Re sinu wa.
Amin.

895 S.M.
Emi o sifi ogo kun ileyi, li Oluwa
awon omo ogun wi.
Hag. 2:7.

1 f Olorun wa tobi,
Eje k‘iyin Re po,
O f‘ile sin Re se bugbe
At‘ibujoko Re

2 f Tempili or‘ofe,
A! won ti dara to!
Awon li ola ilu wa
At‘odi ile wa.

3 cr Ni Sion, Olorun
L‘abo n‘igba ‘ponju
ff Igbala Re ti logo to
N‘nu awon afin Re!

4 mp Bi iponju bade,
cr A o lo si‘le Re;
di A o ranti ore-ofe Re,
Ao wa ‘gbala nibe.
Amin.

896 7.5.7.5.7.5.7.5.8.8.
Ki O si gbo li orun, ibugbe Re,
gbo, ki O si dariji.
I A. Oba 8:30.

1 mp Gb‘alareti nwa ‘simi


Sa wa odo Re;
‘Gba eni ti orun nwo
Gb‘eru re le O;
‘Gba eni nwa alafia
Ke pe oko Re;
‘Gb‘elese ti nwa iye
Wole l‘ese Re;
cr Jo, Oluwa, gbo igbe won
f Lati ibugbe Re l‘orun.

2 mp ‘Gba eni ti aye su


Gb‘okan re s‘oke;
‘Gbat‘ asako ba pada
S‘ife Baba re;
T‘agberaga ba wole
Lati w‘oju Re;
T‘eni ebi kese re
Wa sib‘ite Re
cr Jo, Oluwa, gbo igbe won
f Lati ibugbe Re l‘orun.

3 mp ‘Gbat‘ alejo nwa ‘bugbe


Ti y‘o simi si;
Ti elebi nwa onje,
T‘otosi nw‘oro,
‘Gbat‘ atuko loju 'bu
Wo O fun ‘ranwo;
T‘eni nja l‘oju ogun
Gb‘okan re si O;
cr Jo, Oluwa gbo igbe won
f Lati ibugbe Re l‘orun.

4 mp ‘Gbati eni ti nsise


Li arin ilu,
T‘O1us‘agutan n‘igbe
P‘oko Olorun;
Gba t‘awon alagbara,
T‘adun aye su.
Ti nlepa ayo t‘orun
Pe oko nla ni;
cr Jo, Oluwa, gbo igbe won
f Lati ibugbe Re l‘orun.

5 mp ‘Gbati ewe at‘odo,


Ati arugbo
Ba nsaferi oju Re
Nipa adura;
‘Gbat‘ opo ba nke pe O
N‘nu ‘banuje re
Nigbati alail‘obi
Ko osi re wa;
cr Jo, Oluwa, gbo igbe won
Lati ibugbe Re l‘orun.

6 mp ‘Gba gbogb‘eda nkerora


N‘nu iponju won
Ti omo Re, asako,
Mi imi edun,
T‘ijo Re, t‘on t‘omije
Ba nwa ibugbe,
Ti nfi edun ke wipe
Jesu, jare, wa;
cr Jo, Oluwa, gbo igbe won
f Lati ibugbe Re lorun.
Amin.

897 7.6.7.6.7.6.7.6.
Nitori Ogo Oluwa kun ile Oluwa.
I A. Oba 8:11.

1 mf ‘Wo Eni ti owo Re.


Mu wa d‘ojo oni,
cr Jo tewo gba ope wa,
F‘eti s‘adura wa;
Ki imurasile wa
Fun isin oni je
Lati f‘ara wa fun O
Pel‘ okan isokan.

2 f A yin O fun ile yi


T‘a ko li ase Re;
F‘a won t‘o se iranwo
Fun ise kiko re;
Je ki a ri ogo Re;
Ninu Tempili Re;
di Nitor‘ asan l‘ewa re
Bi O ko si nibe.

3 mf Nigbati a ba npejo
Lati josin nihin,
cr Je k‘ar‘agbara oto
K‘adura wa goke;
K‘osise gb‘okan s‘oke
Si ohun ti orun,
Ki t‘agba t‘ewe l‘okun;
Ki aye mo ‘fe Re

4 mf B‘odun ti nyi lu odun


Ti ife toto npo
Si ile mimo Re yi
Ti a si nranti re,
cr Ki ola at‘ogo Re
Je eyi titi lae
Pe, opolopo t‘ihin
Ri ona s‘odo Re.

5 f ‘Ranwo awon Baba wa,


Ayo on ‘reti wa;
Oluwa fun wa l‘ebun
Opo ojo l‘aye
‘Wo mo edun okan wa,
A mbe niwaju Re
Jo, wa f‘oju rere Re
Se ‘le yi ni Tire.
Amin.

898 L.M
Oluwa Olorun teti sile si adura ti
iranse re ngba loni.
I A. Oba 8:28.

1 mf Pelu wa, Oluwa loni


B‘a ti nya ‘le yi si mimo,
Gbo adura iranse Re,
K‘o si f‘eti si igbe won.
2 Je k‘a ri alafia nihin,
At‘ife ati otito;
Da won t‘a ni tara sile
K‘okan won kun f‘ore-pfe.

3 mp Gbo mi edun awon tire


Ki alare ri isimi;
Gbo gbe onirobinuje
Si bukun fun okan gbogbo.

4 Fi itara kun okan wa,


Si je ki okan wa gbona
‘Gbat‘ a ngbo ‘hinrere nihin;
T‘a si nkede oruko Re.

5 mf So Oku d‘alaye nihin,


K‘odi korin, k‘aditi gbo,
Si fun awon onirele
N‘ifiji at‘alafia.

6 f Se ile yi n‘ibugbe
K‘a ma ri oju Re nihin;
K‘eyi je ile Olorun
Ati enu bode orun.
Amin.

899 L.M.
Nigbati afi ipile ile yi lele, awon pupo
si ho iho nla fun ayo. Esra 3:12.

1 f Olorun, a yin ‘toju Re


Lori agbala mimo yi;
Ota ko gbodo gbogun ti,
K‘o daya fo olusin Re.

2 f A o mo ‘giri yi f‘ola Re,


K‘o ma ho fun ‘yin Re titi;
‘Gbat‘ o ba si sokale wa,
F‘ore-ofe Re kunnu re.

3 mf ‘Gbat‘ojo nla ni ba side,


T‘Olorun y‘o d‘aye lejo,
cr K‘o han fun gbogbo aye pe
f Opo l‘a bi s‘ogo nihin.
Amin.

900 6.5.6.5.D.
Nitoriti afi ipile re sole lori apata.
Mat. 7:25.
1 mf Kristi ni ipile Ile t‘a nko yi;
K‘odi re je ‘gbala
K‘ona re je ‘yin
Ki iloro sowon
L‘oju Oluwa;
K‘okan awon ti nsin
Nihin je mimo.

2 mf Nihin ni k‘Emi Re
Ma gbp eje wa;
K‘alaisan r‘iwosan,
K‘a m‘asako bo;
K‘onirobinuje
Ri ‘dariji gba;
K‘awon t‘o ti pinya
Tun ni irepo.

3 mf Jeki a ri eri
Pe, Ombe nihin;
K‘awon t‘a de l‘ewon
D‘ominira nihin;
cr K‘imole tan nihin
Si awon Tire.
Lati gbe wa soke
Si ohun t‘orun.

4 f Nihin ni k‘a juba


Olorun Baba
Ati Kristi Omo
Pel‘Emi mimo;
Titi gbogbo eda
Y‘o wole fun O,
Ti won o ma yin O;
Oluwa aye.
Amin.

901 12.9.12.9. & Ref.


Solomoni si beresi iko ile Oluwa.
IIKro. 3 :1.

1 mf Oyigiyigi, Oba Onise ‘yanu


Atobiju Olodumare,
Abani-kedun, Oluranlowo alaini
Iwp l‘ope ye, Olugbala
f Dide, Olorun Solomoni, dide,
Ba wa ko ile yi pari,
Je k‘a nipin lati josin nibe
Pelu orin ‘yin on opc.
2 cr Iwo Olorun to bukun fun Jakobu,
Ran wa lowo lori ise yi
Ki ‘lekun orun si, k‘ojo bukun si ro
S‘ori t‘agba t‘ewe Ijo wa

3 f Eje ka fi iyin at ‘ope f‘Oluwa


Fun ore-ofe nla to fun wa
Lati ko ile mimo nigba aye wa
Fun ogo oruko Oluwa.

4 cr Eranti ileri t‘Olugbala wa se


Lat‘enu awon iransc Re
Pe, a ti fi isura nla pamo fun wa
Nibi kokoro ko le ba je.

5 IWO Olorun eleda ohun gbogbo


Je ka ni ipin n‘nu ise yi,
mf Fun wa n‘irepo ati isokan emi.
Lati pari ‗le yi f‘ogo Re

6 mf Bi Baba ti f‘owo ‘tun Re gbe Jesu ga


Leyin t‘ise igbala pari,
cr Fun wa ni ‘segun, ko si gbe ijo yi ga,
K‘O si so di ile irorun.
Amin.

902 8.7.8.7.4.7.
Nitori ile adura li a o ma pe ile mi
fun gbogbo eniyan. Isa. 56:7.

1 f Olorun Baba, Ologo,


T‘O joko lor‘ite lae
Awa omo Re teriba.
A nw‘ojure Re nikan;
ff Oluwa wa,
p Jek‘anu Re han si wa.

2 f Olorun Omo ‘Lugbala,


T‘O duro n‘ite anu,
O ti jeje ojure Re
Nibit‘ eeyan Re ba pe;
ff Alabukun,
p Bukun wab‘ati duro.

3 f Olorun emi, to nwe ni,


‘Mole, Iye, Agbara,
OWO ina mimo loke,
Mu k‘oju Re dan si wa
ff Emi Mimo,
S ago yi ni Tire.
4 f Baba, Omo, ati Emi,
Ife‘sokan, so kale;
Ki ore-ofe Re si wa
SO ile yi di Tire;
ff Jehofa nla,
Ran ogo ‘dahun si wa.
Amin.

903 L.M.
Adura ki adura tabi ebe ki ebe
ti a ba ti odo enikeni gba ...
ki iwo ki o gbo, ki o si dahun.
II Kro. 6:29-30.

1 mf Nihin, l‘oko Re Oluwa,


A ko ‘le ‘rupe yi fun O,
Yan fun ‘bugbe Re pataki,
K‘O si so lowo asise.

2 mp Gb‘eyan Re ba nwa O nihin,


T‘elese mbebe fun iye,
Gbo lat‘ibugbe Re Orun,
Gbat‘O ba gbo, k‘O dariji.

3 mf Gbat‘ojise Re ba nwasu
Ihinrere Jesu nihin,
Nip‘agbara oko Re nla,
K‘a ri ami on ‘se ‘yanu.

4 ‘Gba t‘ohun ewe ban korin,


Hosana s‘Oba won l‘oke,
K‘aye at‘orun gberin na,
Ki angeli ko Hosana.

5 f K‘ogo Re ma f‘ihin ‘le lae


Sibe, ma yan ‘le yi nikan,
K‘ijoba Re d‘okan gbogbo,
T‘ite Re si gbogbo aye.
Amin.

904 L.M.
Nitori nibiti eni meji tabi meta ba
ko ara won jo li oruko mi, nibe li emi
o wa li arin won. Mat. 18:20.

1 mf Olorun Baba, Krist‘Omo,


Ati Emi, Metalokan,
Gba ore ti a mu wa yi,
T‘a fife onigbagbo se.
2 K‘imole oro Re f‘oye
F‘agba ati ewe nihin,
Gbin ore ni s‘okan pupo,
Ti gba ni la lowo ese

3 Nihin, ki Jesu f‘ipa han,


Ti so okun di imole,
K‘O si s‘ilekun ‘fe paya,
T‘o yo si ibukun loke,

4 f Jesu Oluwa, Alade,


‘Wo t‘awon mimo nwole fun,
Gba ore iyin t‘a fun O,
K‘O si f‘ogo Re kun‘le yi.
Amin.

905 7.7.7.7.D,
Ibukun ni fun awon ti ngbe inu
ile re: OD. 84:4.

1 f Alafia fun ‘le yi,


At‘awon ti ngbe ‘nu re:
K‘alafia Olorun
B‘eni alafia gbe.
Jeki Emi sokale;
K‘ibukun na ba le wa!
Om‘alafia, gb‘ade re,
Ekun-rere or‘-ofe.

2 mf Kristi, ‘Wo l‘Oluwa mi,


Je ki nje akede Re;
Ma s‘ai ranti oro Re;
Be won wo, si be mi wo!
K‘igbala wo ile yi,
F‘awon ti ngbe inu re
Gba okan wa low‘ese,
Fi wa se ibugbe Re.

3 mf Mase jek‘ a se are,


Tit‘ileri na y‘o se,
Titi ao fi je Tire
Nipa isodimimo;
cr Fun wan‘ife akotun,
K‘a le ri ‘re t‘o sonu,
K‘a je tempil‘Olorun,
Baba, Omo at‘Emi.
Amin.

906 11.10.11.10.11.10.
E LO wasu ihinrere fun gbogbo eda.
Mk. 16:15.

1 mf Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,


cr F‘anu ja won kuro ninu ese;
Ke f‘awon ti nsina gb‘eni subu ro,
So fun won pe, Jesu le gba won la
p Yo awon ti nsegbe, sajo eni nku,
cr Alanu ni Jesu, yio gbala.

2 mf Bi won tile gan, sibe O nduro


Lati gb‘omo t‘o ronupiwada
p Sa fitara ro won, si ro won jeje,
On o dariji bi won je gbagbo.

3 mf Ero okan eda ti esu te pa


Ni ore-ofe le tun mu pada;
Okan ti o gb‘ogbe, t‘a fowo ife
At‘inu rere soji, y‘o korin.

4 Yo awon ti nsegbe - ise tire ni,


Oluwa yio f‘agbara fun o;
Fi suru ro won pada s‘ona toro,
So f‘asako p‘Olugbala ti ku.
Amin.

907 10.10.10.10.
E wa enyin tikara nyin si apakan,
ki enyin ki o si simi die, Mat. 6:31.

1 mp Ewa sapakan, k‘e simi die,


Mo mo are ati wahala yin;
E nu ogun oju yin nu kuro,
cr K‘e si gb‘agbara n‘nu agbara Mi.

2 mf E takete s‘ohun adun aye.


E wa fun idapo t‘aye ko
mp Enikan wa l‘odo Mi on Baba,
L‘odo Mi on Baba, egbe yin kun.

3 E wa so gbogb‘ohun t‘e se fun mi,


So t‘isegun ati t‘isubu yin;
p Mo mo b‘ise emi ti soro to,
cr Ade t‘o dara t‘on t‘omijeni.

4 mp E wa simi; ajo na jin pupo,


Are o mu yin, e o ku lona;
cr Onje iye wa nihin, ewaje
Nihin l‘omi iye wa, e wa mu.
Amin.
908 L.M
E si kiyesi, Emi wa pelu yin
Nigbagbogbo titi o fi de opin aye
Mat 28:20

1 mf ‗Gbati Jesu g‘oke r‘orun


N‘isegun lori ota Re;
O tu ebun sori aye,
Ore Re si tan kakiri

2 cr Nibe l‘Aposteli ti dide,


Mimo won tayo okiki
Bi won l‘awon eni rele
Ti ns‘alufa at‘oluko

3 f Kristi l‘orisun ebun won


On ni iye or‘ofe won
B‘o ti nf‘owo Re gbe won ro
Won duro sinsin n‘un ‗ponju

4 cr Be n‘iran won ki o dase


Titi aye yo fi dopin;
Nipa won ni Ijo titun
Yo dide, y‘o si ma gbile

5 f Jesu, je ki okan wa mo
Orisun ibukun wonyi;
K‘alufa at‘ijo yin O,
Tit‘aye anipekun
Amin

909 7.6.7.6.d
E ma duro sinsin laiyese. Ki e si mapo
Si ni ise Oluwa nigbagbogbo
I Kor. 15:58

1 mf Oluwa ‗kore emi


Ninu oko aye,
Nibi t‘awon angeli,
Y‘o ko iti won jo,
cr Gb‘awon wonyi fun ‗se Re,
Fi ife s‘okan won,
Je k‘a ti owo won mu,
‗Joba Re yara de.

2 mf Fi won se alagbase
L‘ogba Re, Oluwa
Fun won ni itelorun
Lati sise fun O;
‗Gbat‘ O ba pe won rele
di Je k‘o te won lorun
Pe awon pin n‘nu lala
Ti nmu ‗joba Re bo

3 mf Ma wa pelu won, Baba


Ma ba won gbe Omo
Ma so won, Emi Mimo
Metalokan laelae
di Fi won joye alufa
Lati f‘oto sin O
Si fi ore re kun won
Loni ati laelae

4 mf Wa, iwo Emi Mimo


Fi imole kun wa,
Fi ewu ailabawon
Wo wa ka fun alulau,
Pelu wa b‘a ti duro
N‘nu ile mimo Re;
Ya eeyan Re si mimo
Ni gbogbo ile yi
Amin

910 C.M
Ke enyin fi ara nyin rubo si Olorun,
Eyi ni ise isin nyin ti o tona
Rom. 12:1

1 mf Onise Olorun, dide!


Mo riri Olorun
cr B‘o ti wu k‘ogun gboan to
‗Wo o ja b‘akoni

2 Ilopo ibukun ni fun


Okan eni t‘O so
Pe Olorun mbe l‘oju ‗ja,
‗Gbat‘ oju wa ko ri

3 mf Olorun ju b‘a ti ro lo,


Giga si l‘ona Re;
Eni n‘ife ewe l‘okan,
L‘o le ri ona na

4 cr Mase ka iyin eda si,


Padanu f‘Olorun,
di Jesu jer‘aye nipa egan,
o npe o s‘ona Re,

5 mf Oto ni y‘o leke dandan


Niwon t‘Olorun mbe,
Isolete ni iyemeji;
Ese n‘ifasehin.
Amin

911 C.M
Ibukun Re si mbe lara awon Eniyan Re.
OD 3:8

1 mf Iwo t‘o nmu okan mole


Nipa ‗mole at‘orun wa;
di T‘o si nse iri ibukun
So‘rawon ti nsaferi Re

2 mf Jo masai fi ibukun Re
Fun oluko at‘akeko
Ki ijo Re le je mimo,
K‘atupa Re majo gere

3 F‘okan mimo fun oluko,


Igbagbo, ‗reti at‘ife,
Ki won je ‗nit‘Iwo ti ko,
Ki won le j‘Oluko rere

4 F‘eti igboran f‘akeko,


Okan ‗rele at‘ailetan;
Talaka t‘o kun f‘ebun yi
San ju oba aye yi lo

5 cr Bukun oluso at‘agutan


Ki won j‘okan labe ‗so Re;
Ki won ma f‘okan kan sona
Tit‘aye osi yi y‘o pin

6 Baba b‘awa n‘nu ore Re,


L‘ay yi l‘a o ti logo;
K‘a to koja s‘oke orun
Lao mo ohun ti aiku je
Amin.

912 L.M
Won tete ko fi awon tikarawon fun Oluwa.
II Kor 8:5
1 K‘emi n‘tori eru eniyan
Da se Emi druo n‘nu mi?
Tabi ki njeri f‘Oluwa
L‘oro on ise, laifoya?

2 Ifajuro eniyan le
Mu mi pa or‘Olorun mo?
di Bawo l‘emi y‘o ti se le
Duro loju ibinu Re?

3 cr K‘emi ha din oro Re ku,


K‘o le ba ti aye lara;
Tabi, ki nsa f‘agbelebu,
Ki nle jere ohun aye?

4 mp Olugbala, oju Re ri
Gbogbo ero ‗nu okan mi;
p Ohun kan ha gba mi laya
Faji aye tab‘iyin re?

5 mf Ife Krist ni o nro mi


Lati wa emi t‘o sako;
mp Ki nfi ebe ati ekun
Ja won l‘enu isa oku

6 mp Mo m‘emi atara mi wa
Bi won le wulo f‘oto Re;
cr Mu imo Re se, Oluwa;
K‘a se ‗fe Re, k‘a juba Re,

7 mf Fun mi l‘agbara, Olorun;


Iji ba ja, ara ‗ba san,
Eleri ooto ni un o je
Mo le s‘ohun gbogbo n‘nu Re.
Amin.

913 S.M
Sugbon nitori oro re, emi o ju awon
Na si isale Lk. 5:5

1 Jesu, b‘a nfurugbin,


Oro ‗ye lase Re;
B‘a ti owo Re b‘omirin,
‗Rugbin na y‘o dagba

2 mf Ipa or‘ofe Re
Y‘o mu bisi pupo;
Y‘o so oloto di pupo
Ti nwa fun ogo Re

3 mf Ro ojo ibukun
Ti ihin rere Re,
K‘agbara ti ny‘okan pada
Ba iran Re gbe

4 cr Fun opo eniyan


N‘ife isodotun;
F‘ayo or‘ofe pese won
F‘ayo kikun loke
Amin.

914 S.M.
E di amure nyin, ki fitila nyin si ma tan.
Lk 12:35.

1 mf Iranse Oluwa!
E duro nid‘ise
E toju oro mimo Re,
E ma sona Re sa.

2 Je k‘imole yin, tan,


E tun fitila se!
E damure girigiri,
Oruko Re l‘eru.

3 Sora! l‘ase Jesu;


B‘a ti nso, ko jina;
p B‘o ba kuku ti kan ‗lekun
mp Ki e si fun logan.

4 f Iranse ‘re l‘eni


Ti a ba nipo yi;
Ayo l‘on o fi r‘Oluwa,
Yo f‘ola de l‘ade.

5 mf Kristi tikalare,
Y‘o te tabili fun;
Yo gb‘ori iranse na ga
Larin egbe angel.
Amin.

915 L.M.
Ki emi ki o le mo bi a ti i soro li
akoko fun alare. Isa. 50:4.

1 mf Ko mi Oluwa, bi a ti
Je gbohungbohun oro Re;
B‘o ti wa mi, je k‘emi wa
Awon omo Re t‘o ti nu.

2 To mi, Oluwa, ki nle to


Awon asako si ona;
Bo mi Oluwa, ki nle fi
Manna Re b‘awon t‘ebi npa

3 f Fun mi l‘agbara: fi ese


Mi mule lori apata;
di Ki nle na owo igbala
S‘awon t‘o nri sinu ese

4 mf Ko mi Oluwa, ki nle fi
Eko rere Re k‘elomi;
F'iye f‗oro mi, k'o le fo
De ikoko gbogbo okan

5 f F‘isimi didun Re fun mi,


Ki nle mo, bo ti ye lati
Fi pelepele s‘oro Re
Fun awon ti are ti mu.

6 f Fi ekun ore Re fun mi,


Titi okan mi y‘o fi kun
Fun tara l‘ero at‘oro
Lati kede ‘fe oun ‘yin Re

7 Lo mi, Oluwa, a n‘emi


Bi o ti fe, nigbakugba,
Titi em‘o fi r‘oju Re,
Ti un o pin ninu ogo Re
Amin.

916 S.M.
Alabukun fun ni enyin ti nfunrugbin
niha omi gbogbo. Isa. 32:20.

1 f Fun ‘rugbin l‘owuro,


Ma simi tit‘ ale;
F‘eru on ‘yemeji sile,
Ma fun s‘ibi gbogbo.

2 mf ‘Wo ko mo ‘yi ti nhu,


T‘oro tabi t‘ale
Ore-ofe yoo pamo
‘Bi t‘o wu ko bo si.

3 Yoo si hu jade
L‘ewa tutu yoyo;
Beni y‘o si dagba s‘oke,
Y‘o s‘eso nikeyin.

4 ‘Wo k‘y‘o sise lasan!


Ojo, iri, orun
Yoo jumo si ise po
Fun ikore orun.

5 f Nje nikehin ojo


Nigbat‘ opin ba de,
Awon angel y‘o si wa ko
Ikore lo sile.
Amin.

917 C.M
Niti ise sise, E mase sole.
Rom. 12:11.

1 mf A tun pe mi s‘idi ‘se mi


Un o fayo sa pa mi;
Un o fi okan kan se ‘se mi;
Oluwa, l‘oko Re

2 Iwo l‘opin gbogbo‘se mi‘


‘Wo nikan ni mo ri;
cr Oluwa gba‘se mimo mi
Iwo ni mo se fun.

3 mf Baba, fi oju ife wo


Ohun ti ‘se Tire;
Jesu da ebun t‘emi yi
MO ebo nla Tire

4 B‘a ba so ‘se mi di yiye,


On yio tewo gba
Inu Re y‘o si dun si mi,
Ti mo je omo Re.
Amin.

918 8.7.8.7.8.7.
Emi wa pelu yin ani titi de opin aye.
Mat. 28:20.

1 mf Sin awon onse Re, sin won


W‘oba efufu igbi;
A de won, O da won sile,
Won nlo‘da eru ni‘de:
cr Wa pelu won, wa pelu won,
Apa Re, l‘o le gbala.

2 Won f‘ile at‘ore sile


Ni ase Re Oluwa;
N‘ile ati loju omi
Je Alafehinti won,
cr Jo pelu won, jo pelu won,
Si ma to won lailewu.

3 mp ‘Biti ‘se won ko m‘eso wa,


T‘o dabi ‘se won jasan;
Sunmo won l‘anu Re, Jesu
Mu ireti won duro;
Ran won lowo, ran won lowo,
K‘itara won tun soji.

4 mf N‘nu opolopo isoro,


K‘won gbekele O, Jesu
‘Gbat‘ ise na ba si ngbile,
Ki won mase gberaga;
cr Ma fi won ‘le, ma fi won ‘le
Titi won o r‘oju Re

5 f Nibiti won o fayo ka


Eso irugbin aye;
Nibiti won o wa titi
Lodo Olupamo won;
Pelu ‘segun, pelu ‘segun
Won o maa korin Jesu.
Amin

919 6.6.4.6.6.6.4.
Oluwa si mba won sise
Mk. 16:20.

1 f Oluwa wa mimo,
Ti ogun orun nyin,
Masai gbo wa:
Kerubu, Serafu,
At‘ awon angeli,
S‘odo Re ni won nmu
Iyin won wa.

2 mp Fun oro Re n‘ipa,


Bukun ‘ranse Re yi;
Gba ise re;
Bi Jesu si ti nfi
Ami si Oro re,
Ran Emi Re mimo
Lati fi han.

3 mf B‘odun ti nrekoja,
Ki ayo ma po si
Ju t‘oni lo;
Yan kun ‘nu ilena,
Ran ‘ranse Re lowo,
K‘aye gba oto Re
Oluwa wa.
Amin.

920 C.M.
Ohun na wipe, Kigbe.
Isa. 40:6.

1 mf Jek‘ alore Sion dide


Gba ipe fun ‘ra won;
Jeki won gba ase wuwo
Lat‘enu Oluwa.

2 Ki ‘se ise kekere ni


A nfe oluso si;
O to kun angeli l‘okan,
O kun Jesu lowo.

3 Won nso okan ti Oluwa


F‘ogo orun ‘le fun
Okan ti yio wa titi lae
N‘nu ayo tab‘egbe.

4 mp K‘awon pa le ri Jesu na
Bi Olugbala won;
Si s‘okan won l‘ojojumo
Ki won le SO fun O
Amin.

921 L.M.
Ki enyin ki o be Oluwa Ikore,
ki o le ran alagbase sinu ikore Re.
Lk. 10:2.

1 mp Olorun ‘kore, te ‘ti Re.


F‘ara Re han l‘ogun Sion;
Ran ojise t‘o n‘itara,
T‘o yara lati gb‘ase Re

2 mp Wo wa l‘oju Oluwa wa,


Ikore pon, o nre dede;
Ile nla si siwaju wa,
Ise po, osise kere.

3 mp Fi owo agbara Re to
Omo Sion nibi gbogbo,
Bi alore ‘gbala ofe,
Ki won bukun iran kiku.
Amin.

922 L.M.
E gba awon ti nse olori yin gbo,
ki e sifi ori yin bale, nitori won nso eso
nitori okan yin. Heb. 13:17.

1 mf Owo l‘eni ororo Re,


L‘ojise oro mimo Re
Ipo eni owo l‘o wa.
Jek‘ a f‘iyin at‘ola fun.

2 Ipo elege n‘ipo re,


ASO ti ko fe abawon.
Jek‘ a fi ife ran lowo,
K‘a fi irele gb'oro re.

3 Niwon b‘o ti wu O lati


Fi oluso emi wa,
p Fun ni suru lati to wa,
Ati opo if‘ara da.

4 mp Ma jek‘ise wa mu binu,
Ki iwawa tan ni suru;
Fun l'agbara bi ojo re,
B‘ipo re, fun lor' ofe Re.

5 mp Jek‘ a r‘ewa Re lara re,


K‘o ma ran n‘nu iwa pele,
K‘o mo ‘po re bi oluso,
K‘a mo ti wa b‘agutan re
Amin.

923 S.M.
E ma ko won lati ma kiyesi ohun gbogbo.
Mat. 28:20.

1 Eyin ‘ranse Kristi,


Gbo ohun ipe Re:
E tele Ona t‘O fi han,
Eyi t‘a pe yin si.

2 mf Baba ti eyin nsin,


Alagbara ni se;
E gbekele ileri Re,
E ja bi okunrin.

3 LO f‘Olugbala han,
Ati anu nla Re.
F‘awon otosi elese.
Ninu omo Adam‘

4 f L‘oruko Jesu wa,


A ki yin, Ona ‗re!
A mbe Eni t‘Oran yin lo,
K‘O BUSI ISE yin.
Amin.
924 11.11.11.11 & Ref.
Nitoripe Oluwa Olorun re,
On ni O mba o lo. Deut. 31:6.

1 mf Jesu y‘o pelu re l‘ona re gbogbo,


Jesu y‘o pelu re, y‘o si maa to O
Larin asale ati l‘ori oke,
Jesu y‘o wa pelu re nigba gbogbo.
f Jesu y‘o pelu re, Jesu y‘o pelu re,
Y‘o je ore at‘olutunu fun o;
Jesu y‘o pelu re, Jesu y‘o pelu re;
Jesu y‘o pelu re de opin.

2 Jesu y‘o pelu re l‘ona re gbogbo


Jesu y‘o pelu re, y‘o si di o mu
mp Larin afonifoji ibanuje,
Jesu y‘o pelu re, ma so ‘reti nu.

3 Jesu y‘o pelu re l‘ona re gbogbo.


Jesu y‘o pelu re, l‘ona ajo re,
cr Larin isan ‘danwo s‘ona ilu ni,
Jesu y‘o pelu re, sa gbeke re l‘E.
Amin.

925 L.M.
Olorun igbala wa, Eni ti ise igbekele eniyan gbogbo opin ile aye ati okun ti o jina rere.
OD. 65:5.

1 Baba, jowo, gb‘adura wa,


Bi a ti nlo l‘oju omi;
IWO maa je ebute wa,
At‘ile wa l‘oju omi.

2 p Jesu Olugbala,‘WO ti
O ti mu ‘ji dake roro,
cr Maa je ayo fun asofo,
F‘isimi f‘okan aibale.

3 mf ‘WO Emi Mimo, Eni ti,


O ra baba l‘oju omi,
Pase ‘bukun l‘akoko yi,
Fi ipa Re mu wa soji.

4 f ‘WO Olorun Metalokan,


Ti awa nsin, ti awa mbo
Maa se abo wa laye yi
Ati ayo wa li orun.
Amin.

926 8.8.8.D.
Awon ti o nsise ninu omi nla won ri
ife Oluwa, ati ise iyanu Re ninu ibu.
OD. 107:23-24.

1 mf Baba wa Olodumare,
‘Wo t‘O kawo igbi omi,
‘WO t‘O ti f‘ipo okun fun,
Ti ko le re ibe koja;
p.cr Gbo tiwa, ‘gbat‘a nkepe O
di F‘awon t‘o wa l‘oju omi.

2 mf Olugbala ‘Wo t‘oro Re


Mu igbi omi pa roro,
IWO t‘O rin l‘ori omi,
T‘O sun b‘enipe ko si nkan
p.cr Gbo ti wa, ‘gbat‘ a nkepe O
di F‘awon t‘o wa l‘oju omi.

3 mf ‘WO Emi Mimo, t‘o rado


B‘omi aye ni ‘jo kini;
T‘O mu ‘binu re pa roro
Oluwa ‘mole at‘iye
p.cr Gbo tiwa, ‘gbat‘a nkepe O
di F‘awon t‘o wa l‘oju omi.

4 f Metalokan, alagbara;
Dabobo won ninu ewu,
L‘OWO apata at‘iji,
L‘OWO ina ati ota;
ff Si je k‘a maa korin ‘ yin Re
di L‘or‘ ile ati lor‘ omi.
Amin.

927 9.8.8.9.& Ref.


Oluwa On ni o nlo saju re;
On ni yio pelu re. Deut. 31:8.

1 cr K ‘Olorun so o k‘a tun pade!


Ki imoran Re gbe o ro;
K‘o ka o mo agutan Re;
K‘Olorun so o k‘a tun pade!
mf K‘a pade ...... K‘a pade
K‘a pade...... l‘ese Jesu;
K‘a pade...... K‘a pade!
K‘Olorun so o k‘a tun pade!

2 cr K‘Olorun so o k‘a tun pade!


K‘o f‘iye Re dabobo O,
K‘o maa pese fun aini re,
K‘Olorun so o k‘a tun pade!
3 K‘Olorun so o k'a tun pade!
mp Nigbat‘ ewu ba yi o ka,
cr K‘o f‘owo ‗fe Re gba o mu,
K‘Olorun so o, k‘a tun pade.

4 K‘Olorun so o k‘a tun pade.


K‘o fi ife rado bo o,
K‘o opa oro Iku fun o
K‘Olorun so o, ka tun pade!
Amin.

928 L.M
Abo mi mbe lodo Olprun
O.D 7.10.
1 mf Pelu mi nibiti mo nlo;
KO mi l‘ohun t‘emi o pe
Pase ero at‘oro mi
K‘o f ese mi le ona Re

2 Fi opo ife Re fun mi,


Maa se alabo mi laelae
Fi edidi Re s‘aya mi,
Jeki Emi Re pelu mi.

3 KO mi bi a ti gbadura,
Si jeki emi gba O gbo;
Ki nkorira nkan t‘O ko fe
Ki n si fe ohun ti O fe
Amin.

929 S.M.
Ohun rere ni lati ma fi ope
fun Oluwa. OD. 92:1

1 cr A mbe l‘aye sibe,


A si tun 'ra wa ri?
Ogo at‘iyin fun Jesu
Fun ore ofe Re!

2 mf Oluwa pa wa mo
S'ekun ‗gbala nihin
f A tun dapo k‘a yin Jesu,
A mbe niwaju Re

3 mp Iponju t‘a ti ri,


Iya ti a ti je
Ija l‘ode, eru n‘inu
Leyin t‘ape kehin!
4 mf Sugbon Jesu fi ‗fe
Y‘o wa n‘nu gbogbo re;
O si nran wa lowo sibe
O nap emi wa mo

5 f E je ki a maa fi
‘Rapada Re s‘ogo
Ti y‘o gba wa la de opin,
‘Gbat‘a ki o se mo

6 di K‘a gbe agbelebu,


Titi a o gb‘ade;
K‘a ka ohun gbogbo s‘ofo
K‘ale jere Jesu.
Amin.

930 S.M.
Ohun o si fun yin li Olutunu miran,
ki o le ma ba yin gbe. Jn. 14:16.

1 di Jesu‘Wo li a nwo,
A d‘ileri Re mu,
Pe, ‘Wo y‘o wa larin awa
T‘o pejo l‘oko Re.

2 cr Ooko Re n‘igbala,
Ti a nwa lati mo;
mf lye, alafia, f‘oko Re,
At‘ife ailopin.

3 mf Ki se ni ‘gberaga,
Tab‘ ainife tooto
L‘a ya kuro l‘ona t‘eda.
T‘a wa pade nihin.

4 A wa gba or‘-ofe
T‘O fi fun wa l‘ofe;
cr A pejo l‘aye n‘tori Re,
K‘ale pejo l‘orun.

5 A mo p‘O wa nihin,
cr Sugbon f‘ara Re han!
Oluwa, jeki gbogbo wa
Mo itunu nla Re.

6 p K'ohun isoji Re
Pa oku ese run;
cr Si mu okan wa yo de ‘nu,
N‘ireti ‘ fe pipe!
Amin.
931 S.M.
Alafia mi ni mo fi fun yin.
Jn. 14:27.

1 mp A o pinya l‘ara lo
S‘oniruru ilu
mf Sugbon awon ore Jesu
Wa n‘isokan emi.

2 Jesu, Olori wa,


L‘O da okan wa po,
Awa t‘a mba rin ni mimo
L‘O so d‘okan l‘emi.

3 cr Jek‘a te siwaju
Ninu ise Jesu;
K‘a ma tele Olusegun,
K‘a bale segun si!

4 mf Ogba Oluwa mbe


Niwaju On ‘se Re;
Awa si nwo ere nla na,
Ti a nlo ba loke.

5 cr K‘ife at‘ere wa
Goke nigbagbogbo.
Lati d‘ebute‘simi ni
Nibiti ‘se wa pin.

6 Nibe n‘ise wa tan,


Iya oun ‘rora wa!
L‘ebute ayeraye ni;
A ki yoo pinya mo.

7 Ilu alafia,
T‘awon mimo pade!
mf Nibe l‘a or‘oju ara wa,
T‘a o yo mo ara wa.

8 T‘awa-t‘ijo ‘saju
L‘ao jumo gba ‘bukun,
Ninu ayo l‘ao tun wo
Isimi ailopin.
Amin.

932 6.6.8.4.
Ki Oluwa alafia tikarare, ma fun yin
ni alafia nigbagbogbo.
II Tes. 3:16.
1 mp Oro alafia
L‘a fi sin yin, ara,
cr K‘ alafia bi odo nla
Ma ba yin lo.

2 mp N‘nu oro adura,


A fawon ara wa
Le iso Oluwa lowo;
Ore tooto.

3 mf Oro ife didun


L‘a fi p‘odigbose,
Ife wa ati t‘Olorun
Y‘o ba won gbe.

4 f Oro ‘gbagbo lile,


Ni igbekele wa
Pe, Oluwa y‘o se ‘ranwo
Nigba gbogbo.

5 Oro ‘reti didun


Y‘o mu ‘pinya wa dun,
Y‘o SO ayo t‘o le dun ju
Ayo t‘aye.

6 mf O digbose ara;
N‘ife ati ‘gbagbo
p Tit‘ao fi tun pade l‘oke
N‘ile l‘orun.
Amin.

933 c.m.
O mu won wa si ebute ife won.
OD. 107:30.

1 mf Olorun wa n‘nu oko


Larin omi jinjin,
S‘OLUSO wa ba ti nwa lo,
Ninu ajin oru.

2 Eru ko ye ki o ba wa,
Larin iji ti nja,
Niwon gba t‘ O wa nitosi
Larin omi ti nru.

3 Iparoro ati Iji,


T‘o nkoja lori ‘le
IWO ni o da gbogbo won,
Won wa nikuwo Re.
4 Nigbat' awon Apositeli,
Wa lori ‘gbi okun,
Ase kan lat‘odo Re wa,
Mu dake roro wa.

5 mp Gbati iji to buruju,


Banru l‘atokan wa,
Oluwa ma sai ba wa gbo
F‘alafia ba wa gbe.

6 mf Ninu wahala aye yi,


Ma se amona wa,
Titi a o fide‘le rere,
Nibi t‘ese ko si.
Amin.

934 7.7.7.7.
Ki Oluwa ki o so temitire nigbati a o ya
kuro lodo ara wa.
Gen. 31:49.

1 mf Ni akoko ipinya
Jeki a fi ara wa,
S‘abe oju at‘okan,
Ore korikosun wa.

2 p Jesu gbo adura wa,


‘WO ti nso agutan Re,
K‘anu atitoju Re,
Pa gbogbo okan wa mo

3 mf K‘a l‘agbara n‘ipa Re,


F‘adun s‘irora gbogbo,
K‘o si da emi wa si,
Titi ao fi tun pade.
Amin.

935 10.10.10.6.
Ati opolopo ninu awon ti o sun ninu
erupe ile ni yio ji, awon miran s 'iye ainippkun,
Dan. 12:2.

1 mf Ma sun, Olufe; ko si ina simi


Gb‘ori re le aya olugbala
A fe o sugbon Jesu fe o ju,
p Sun 're, sun ‘re, sun ‘re.

2 mf Orun re dun bi orun omode,


Iwo ki yo si ji si ekun mo
Isinmi t‘o daju n‘isimi re,
p Sun're, sun‘re, sun‘re.

3 p Tit‘ a o ka okunkun aye kuro


Titi ao fi ko ikore ‘wole,
Titi oye aye yio fi la,
p Sun ‘re, sun ‘re, sun ‘re.

4 mf Titi orun ajinde y‘o fi yo


T‘awon oku n‘nu Jesu y‘o dide
On y‘o si wa ninu olanla Re,
Sun ‘re, sun ‘re, sun ‘re.

5 mf Titi ewa orun ‘yo je tire,


cr Ti iwo o ma ran ninu ogo
f Oluwa y‘o de o l‘ade wura
p Sun ‘re, sun ‘re, sun ‘re.

6 mf O d‘owuro sa ni, olufe mi,


A tun fere ri ‘ra na: nibiti
di Ipinya ati ituka ko si
p Sun ‘re, sun ‘re, sun ‘re.

7 mf Tit‘ ao fi pade niwaju ‘te Re


Nin ‘aso igunwa awon Tire
Tit‘ a o mo gege bi a ti mo wa,
p Sun ‘re, sun ‘re, sun ‘re.
Amin.

936 7.77.7.
O si wi fun u pe ma sokun mo.
Lk. 7:13.

1 p Gba t‘ a kun fun ‘banuje,


‘Gb‘omije nsan l‘oju wa,
‘Gbat‘ a nsokun t‘a nsofo,
cr Olugbala, gbo ti wa.

2 p ‘Wo ti gbe ara wa wo,


O si mo ‘banuje wa;
O ti sokun bi awa,
cr Olugbala; gbo ti wa.

3 pp ‘Wo ti teriba fun‘ku,


‘Wo ti t‘eje Re sile
A te O si posi ri
cr Olugbala, gbo ti wa

4 p ‘Gbati okan wa ba baje


Nitori ese t‘a da
‗Gbati eru ba b‘okan wa,
cr Olugbala, gbo ti wa

5 p ‗Wo ti mo eru ese,


Ese ti ki se Tire
Eru ese na l‘O gbe,
cr Olugbala, gbo ti wa

6 f O ti silekun iku
O ti setutu f‘ese
ff O wa lowo otun Baba,
cr Olugbala, gbo ti wa
Amin.

937 L.M
Won wo inu alafia; Won simi lori
akete won. Isa. 57:2.

1 mp Igba asale ti dun to,


Ti ara tu ohun gbogbo,
‘Gbati itansan orun ale
Ba ntan mole s‘ohun gbogbo!

2 Beni ‘keyin onigbagbo,


On a simi l‘alafia;
cr lgbagbo t‘o gbona janjan,
A mole ninu okan re.

3 mp Imole kan mo l‘oju Re,


Erin si be ni enu re;
O nfede t‘ahon wa ko mo,
Soro ogo t‘o sunmo ‘le.

4 cr ltansan‘mole t‘orun wa
Lati gba ni ‘yanju l‘ona
Awon angel duro yi ka
Lati gbe lo s‘ibugbe won

5 mp Oluwa, je k‘a lo bayi,


K‘a ba O yo, k‘a r‘oju Re;
Te aworan Re s‘okan wa
Si ko wa b‘a ti ba O rin.
Amin.

938 7.7.7.7.
Li owo Re ni mo fi emi mi le.
OD. 31:5.

1 mp Lala alagba se tan;


Ojo ogun ti pari;
cr L‘ebute jinjin rere
Ni oko re ti gun si,
Baba l‘abe itoju Re,
L‘awa f‘iranse Re yi si.

2 mf N‘ibe l‘are won l‘ekun


Nibe, won m‘ohun gbogbo
di Onidajo ododo
Ndan se aye wo nibe.

3 mf Nibe l‘Olus‘agutan
Nko awon agutan lo,
di Nibe l‘o ndabobo won,
Koriko ko le de ‘be.

4 mp Nibe l‘awon elese,


Ti nteju m‘agbelebu
cr Y‘o mo ife Kristi tan
L‘ese Re ni Paradise

5 mf Nibe l‘agbara Esu,


Ko le b‘ayo won je mo
Kristi Jesu sa nso nwon
On t‘o lu fun‘dande won.

6 pp ―Erupe fun erupe‘‘


L‘ede wa, nisisiyi;
A te sile lati sun
cr Titi d‘ojo ajinde.
Amin.

939 D.S.M.
O seun, iwo omo odo rere ati
Olotito..... bo sinu ayo Oluwa re
Mat. 25:21.

1 mp ―Ranse Olorun, seun;


Simi n‘nu lala re;
mf Iwo ti ja, o si segun;
Bo s‘ayo Baba re.‖
Ohun na de loru,
O dide lati gbo;
p Ofa iku si wo l‘ara,
pp Osubu, ko beru.

2 f Igbe ta loganjo,
―Pade Olorun re.‖
O Ji, o ri Balogun re;
N‘n‘ adura on ‘gbagbo,
cr Okan re nde wiri,
O bo amo sile,
Gbat‘ ile mo, ago ara
p Si sun sile l‘oku.

3 f ‗Rora iku koja


Lara at‘ise tan;
Ojo ogun jija pari,
Okan re r‘alafia
f Omo-gun Krist‘, o seun
Ma korin ayo sa!
ff Smi lodo Olugbala
cr Simi titi aye
Amin.

940 6.6.6.6
Ibukun ni fun oku ti o ku nipa ti Oluwa.
Ifi. 14:13.

1 p Ibukun ni f‘oku
T‘o simi le Jesu
Awon t‘o gb‘ori won
Le okan aya Re

2 mf Iran ‘bukun l‘eyi


Ko si b‘oju l‘arin,
Won ri Eni ‘mole
Ti won ti fe l‘airi.

3 Won bo lowo aye


Pelu aniyan re;
Won bo lowo ewu
T‘o rin l‘osan, l‘oru.

4 mp Oluso-Agutan
Nibit‘ iji ki ja,
Mu won lo si papa
L‘eba omi iye.

5 Lor‘ iboji won


L‘awa nsokun loni
Won j‘en ‘ire fun wa
T‘a ki y‘o gbagbe lae.

6 mp A k‘y‘o gb‘ohun won mo;


Ohun ife didun
Lat‘ oni lo, aye
Ki o tun mo won mo

7 cr Eyin oninure,
E fi wa sile lo
f A o sokun yin titi
ff Jesu pa sokun ri.

8 Sugbon a fe gb'ohub
Olodumare na;
Y‘o ko, y‘o si wipe,
"E jinde, e si yo‖
Amin.

941 L.M.
Ranti Elede re nisisiyi li ojo ewe re.
A. Oni 12:1.

1 A ko ni ‘bugbe kan nihin,


Onile e rora yanran;
B‘o fi gbogb‘ aye ko Garet,
Ese mefa ni busun wa.

2 A ko ni ‘bugbe kan nihin,


Or‘aye fowoba f‘ile
Ni hooho la sa w‘aye
Ni hooho lao pada lo.

3 A ko ni ‘bugbe kan nihin


O ko gbagbo p‘ajo l‘o wa!
Lo wo ‘boji w‘awon to sun,
Awon ni won de ‘bi simi.
Amin

942 L.M
Adorin odun, ni iye ojo odun wa.
OD. 90:10.

1 mf Olorun lat‘ irandiran,


‘Wo n‘isimi at‘abo wa,
K‘a to da orun at‘aye.
Giga ni ife Re l‘oke.

2 mf O ti njoba k‘igba to wa,


Tabi k‘a to da eniyan;
Ijoba Re y‘o wa laelae,
‘Gbat‘ igba at‘aye ba pin.

3 mf Iku, bi odo, ngba wa lo,


Aye wa bi itan lasan,
O dab‘itanna owuro,
Ti a ke lu ‘le, t‘o si ro.

4 mf Jek‘a mo ailera eda


K‘O sun ojo wa siwaju
p Tit‘ ao fi mura de iku,
Nipa ‘wenumo or‘-ofe
Amin.

943 7.6.7.7.6.
Goke Jordani. Jos. 3:17.

1 mf A! won ti gun s‘ebute,


p Loke orun; Loke orun;
mf Ebi ko ni pa won mo,
Won bo lowo irora
f Loke orun; Loke orun.

2 A! Won ko wa fitila,
p Loke orun; Loke orun;
‘Mole ni l‘ojo gbogbo,
Jesu si n‘Imole won,
f Loke orun; Loke orun.

3 A! Wura n‘ita won je,


p Loke orun; Loke orun;
Ogo ‘be si po pupo,
Agbo Jesu ni won je
f Loke orun; Loke orun.

4 A! Otutu ki mu won,
p Loke orun; Loke orun;
Owore won ti koja,
Gbogbo ojo l‘o dara;
f Loke orun; Loke orun.

5 A! Won dekun ija ‘ja,


p Loke orun; Loke o1run;
Jesu l‘o ti gba won la,
T‘awon Tire l‘o si nrin,
Loke orun; Loke orun.

6 A! won ko ni sokun mo,


p Loke orun; Loke orun;
Jesu sa wa lodo won,
Lodo Re ni ayo wa,
f Loke orun; Loke orun.

7 A! A o dapo mo won,
p Loke orun; Loke orun;
A nreti akoko wa,
f ‘Gba Oluwa ba pe ni
di S‘oke orun; S‘oke orun.
Amin.
944 L.M
Emi nku li ojojumo.
IKor. 15:31.

1 mp Bi agogo ofo t‘a nlu,


Ti npe okan yi koja lo,
K‘olukuluku bi ‘ra re,
―Mo ha setan b‘iku pe mi?

2 mp Kin fohun ti mo fe sile,


Ki nlo si d‘ite idajo?
Ki ngbohun Onidajo na,
Ti y‘o so ipo mi fun mi.‖

3 p Ara mi ha gba, b‘o wipe,


―Lo lodo mi eni egun?‖
cr Sinu ina t‘a ti pese
Fun Esu ati ogun re?‖

4 f Jesu Oluwa, jo gba mi,


Iwo ni mo gbeke mi le;
Ko mi ki nr‘ona ewu yi,
Ko mi ki mba O gbe titi.
Amin.

945 C.M.
Ni kutukutu o li aWO lara, o si dagba soke,
li asale, a kee lule, O si ro.
OD. 90:6.

1 p Itana t‘o bo‘gbe l‘aso,


T‘o tutu yoyo be;
cr Gba doje ba kan, a si ku,
Asubu, asiro

2 Apere yi ye f‘ara wa,


B‘or‘ Olorun ti wi;
K‘omode at‘agbalagba
p Mo, ‘ra won l‘eweko.

3 p A! ma gbekele emi re,


Ma pe ‘gba re ntire;
cr Yika l‘a nri doje iku,
O mbe ‘gberun lule.

4 Eyin t‘a dasi di oni,


p Laipe, emi y‘o pin,
f Mura k‘e si gbon l‘akoko,
K‘iko iku to de.
5 Koriko, b‘oku ki jimo;
E ku lati tun ye;
p A! b‘iku lo je ‘lekun nko
S‘irora ailopin!

6 f Oluwa, je k‘a jipe Re,


K‘a kuro n‘nu ese;
Gbat‘ a lule bi koriko,
K‘okan wa yo si O.
Amin.

946 S.M.
Sisun li osun. Lk. 8:52.

1 mf O sun, ni Jesu wi
Nipa ti Lasaru
Eni t‘O ku, ti a ti sin,
T‘ati te s‘iboji.

2 di Oku ojo merin


Sun ni, loju Jesu;
cr On l‘ Ajinde ati Iye
Fun awon t‘o gba gbo

3 mf Ore Jesu ki ku,


Won a ma parada,
Kuro ni kokoro ile
S‘ohun ti nfo l‘oke.

4 di Sun, ara, olufe,


Jesu duro ti o,
cr Ma foya, O ti s‘eleri
Ajinde f‘eni Re.

5 mf O fere gb‘ohun na,


Lat‘ oju orun re,
Ohun didun Jesu ti y‘
Pe o si ajinde.

6 cr A ko ni baraje
Bi alainireti,
Od‘owuro l‘a o ki o.
Sun re, ara, sun re.

7 mp Awa pelu y‘o sun


Li akoko tiwa:
cr A! k‘ile mo ba gbogbo wa
L‘ese Olugbala.
Amin.
947 P.M.
Emi yio si pada to Olorun ti ofi i funni.
A. Oni. 12:7.

1 mp A ra, iwo si / waju wa lo,


Emi re mi / mo si ti fo lo,
Sibiti ko ni / s‘ekun mo;
Ti / ko si irora.

2 O bo lowo / eru ara


Ati lowo / aniyan aye:
di Nib‘eni-buburu / ye yonu,
p Ti a /lare si simi.

3 mp ‘Wo ti rin ajo / aye ja,


O ti / gb‘agbelebu re;
cr Krist ti fi ese re / le ona,
Lati / de ib‘isimi.

4 mp Bi Lasaru / l‘o si sun,


L'a / kaya Baba re,
di Nib‘ eni-buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si simi.

5 mf Ese ko le / ba o je mo,
I / yemeji d‘opin;
Igbagbo re ni / nu Kristi
At‘Emi / ko ni ye mo lae

6 L‘orun lohun / n‘iwo o ba


Awon ore / t‘o ti lo saju;
di Nib‘ eni-buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si simi.

7 Alufa ti wi ni / sisiyi pe,


mp Eru feru, e / rupe ferupe;
Awa si ko e / rupe bo o,
A si / sami s'ori re.

8 cr Sugbon emi re / ti fo lo,


SO / do awon mimo;
di Nib‘eni-buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si simi.

9 mf ‘Gbat‘ Olu / wa ba si pe
A / wa t‘o ku lehin;
Oluwa wa, / awa be O
K‘a /yema ba waje,

10 K‘olukuluku wa, b‘a/rawayi,


Le ri / aye lodo Re,
di Nib‘ eni-buburu / ye yonu,
p Ti a / lare si simi.
Amin.

948 S.M.
Awon emi, nipa igbagbo ati suru, li o jogun
ileri wonni.
Heb. 6:12.

1 mf F‘awon eniyan Re,


T‘o ti Faye sile;
Awon t‘o mo O, to sin O,
Gba orin iyin wa.

2 F‘awon eniyan Re,


Gba ohun ope wa;
Awon t‘o fi O s‘esan won,
Won ku n‘igbagbo Re.

3 mf Ni gbogbo aye won


‘Wo ni won nwo loju;
Emi Mimo Re l‘o nko won
Lati s‘ohun gbogbo.

4 f Fun eyi, Oluwa


cr A nyin oruko Re;
Je k‘a ma tele iwa won,
di Ki a le ku bi won.
Amin.

949 10.10.10.4.
A fi awosanma fi eri pupo yi wa ka
Heb. 12:1.

1 mf F‘awon eniyan Re t‘o lo simi;


Awon ti o fi ‘gbagbo jewo Re,
f K‘a yin oruko Re; Olugbala
Aleluya!

2 Iwo l‘apata won at‘odi won,


IWO ni Balogun won l‘oju ‘ja,
CR IWQ ni imole okunkun won
Aleluya!

3 mp Je ki awon om‘ogun Re l‘aye


cr Jagun nitoto b‘awon ti ‘gbani;
f Ki won le gba ade ogo bi won
Aleluya!
4 mf Idapo ibukun wo lo to yi,
cr Awa nja n‘ihin, awon nyo
f Be tire kanna l‘awa at‘awon – Aleluya!

5 mf ‘Gbat‘ ija ba ngbona, ti ogun nle,


p A dabi eni ngb‘orin ayo won;
cr Igboya a si de, at‘agbara Aleluya!

6 p Ojo nlo, orun wa fere wo na,


Awon ajagun toto y‘o simi.
Didun ni isimi paradise-Aleluya!

7 f Leyin eyi, ojo ayo kan mbo,


Awon mimo y‘o dide n‘nu ogo;
Oba ogo yio wa larin won-Aleluya!

8 ff Lat‘opin ile lat‘opin okun,


Ogunlogo nro wo ‘bode Pearli;
Won nyin Baba, Omo ati Emi-Aleluya!
Amin.

950 8.7.8.7.D.
Ohun ogo li a nso ni tire, ilu Olorun.
OD. 87:3

1 f Ohun ogo Re l‘a nroyin,


Sion, ti Olorun wa;
Oro Eni t‘a ‘ko le ye,
Se o ye fun ‘bugbe Re
‘Pile re mbe lor‘Apata,
Kini, le mi ‘simi re?
A f‘odi ‘gbala yi o ka
K‘o le ma rin ota re;

2 Wo! omi ‘ye ti nsan lati


Isun ijinle ‘fe wa,
O to fun gbogbo omo re
Eru aini ko si mo;
Tal‘ o le re, ‘gba odo na
Ba nsan, t‘o le pongbe re?
Or‘-ofe Olodumare
Ki ye lat‘ irandiran.

3 cr Olugbala, b‘O ba ka mi
Kun awon ara Sion
B‘aye nkegan, t‘o si nsata,
Un'o f‘itiju na s‘ogo;
p Sisa l‘ohun afe aye,
Pelu ogo asan re,
f Isura toto at‘ayo,
Kik‘omo Sion l‘o mo
Amin

951 7.5.6.6.7.7.7.7.
Ninu ile baba mi, opolopo ibugbe
lo wa. Jn. 14:2.

1 f Ile ailopin kan wa,


T‘o ndan, t‘o dara;
Nib‘ayo pipe wa,
Ko si oru nibe,
Awon Angeli si nkorin
Nigbagbogbo yi ‘te ka;
cr Nigbawo ni un o ri o
Ile didan, didan yi?
ff Ile didan yi,
Ile mimo yi,
Ile igbala wa,
Ibugbe ogo!

2 mf Itanna didun wa n‘be,


N‘ile didan yi;
Awon omode nko
Orin iyin Jesu;
f A! b‘orin na ti dun to;
Won y‘ite funfun na ka;
Nigbawo ni un o ri o,
Ile didan, didan yi?

3 cr Laipe ngo dapo mo won


Ni oke orun;
mf Kristi ni ‘gbala mi
Ese ti un o beru?
f Laipe oju mi y‘o ri
B‘o ti joko lor‘ite;
‘Gbana emi o ri O
Ile didan, didan yi.
Amin.

952 8.7.8.7.
Olorun yio si nu omije gbogbo nu
kuro li oju won. Ifi. 21:4.

1 mf Ibanuje ko si l‘orun,
Beni ko si ipinya
cr Fun awon ta ti dariji;
Ekun ki y‘o si l‘orun.
Ibanuje ko si ni ‘lu na,
Beni ailera ko si,
f ‘Tori gbogbo ilu naje imole
‘Tori ekun ko si l‘orun.

2 mf Aisedede ko si nibe,
Ko s‘oju t‘o n‘omije
‘Tori itelorun y‘o wa;
Ekun ki y‘o si l‘orun

3 cr Ko si ‘robinuje l‘oke,
Ko si si imi-edun;
A ki y‘o s‘oro kikoro,

4 di Ekun ki y‘o si l‘orun.


‘Banuje kun okan nihin,
‘Tori ipinya ti mbe;
Sugbon ayo l‘o wa l‘ohun,
Ekun ki y‘o si l‘orun.
Amin.

953 15.11.15.11.& Ref.


Nitori ipeyo dun, a o siji awon oku dide.
I Kor. 15:52.

1 mf Gbati ipe Oluwa ba dun, t‘aye y‘o si fo


Lo,
Ti imole Ojo titun y‘o si de;
Nigbati awon omo igbala ba pejo l‘oke,
T‘a ba si p‘oruko nibe, uno wa m‘be,
f ‘Gbat‘ a ba p‘oruko l‘ohun,
‘Gbat‘ a ba p‘oruko l‘ohun,
‘Gbat‘ a ba p‘oruko l‘ohun,
cr Nipa ore-ofe nikan, un o wa n‘be.

2 mf L‘oro ojo na t‘awon oku n‘nu Kristi y‘o


jinde,
Ti won y‘o si pin n‘nu ogo ajinde;
‘Gbati awon ayanfe y‘o peji si ode orun,
T‘a ba si p‘oruko l‘ohun, un o wa n‘be.

3 cr Jeki a fi gbogbo akoko wa sise f‘Oluwa


Jeki a royin ife iyanu Re;
Nigbati a ba si pari ire ije wa l‘aye,
mf T‘a'ba si p‘oruko l‘ohun, un o wa n‘be.
Amin.

954 10.10.10.10.
Lati isisiyi lo, a fi ade ododo lele fun mi.
II Tim. 4:8.

1 cr Gbat‘ise on ‘danwo mi ba pari


Ti mo si gun s‘ebute rere na;
Ki nsa le sunm‘Oluwa ti mo fe
Eyi y‘o je ogo fun mi titi
mf Eyi y‘o je ogo fun mi
Ogo fun mi, ogo fun mi,
Ti un o w‘oju Re nipa or‘ofe
Eyi y‘o je ogo fun mi.

2 mf Nigba ore ofe Re ailopin


Ba fi ipo kan li orun fun mi,
cr Ki nsale wa n‘be lati w‘oju Re
Eyi y‘o je ogo fun mi titi.

3 mf Ore ti mo fi fe y‘o wa nibe;


Ayo bi odo yio san yi mi ka;
f Mo mo pe un o r‘ayo lodo Jesu
Eyi y‘o je ogo fun mi titi.
Amin.

955 15.15.15.15. & Ref.


O sifi orin titun si mi li enu, ani orin iyin si
Olorun wa. OD. 40:3.

1 f Orin mbe li orun, iru eyiti awa ko mo,


Nibiti awon angeli nkorin ‘yin
s‘Odagutan
Harpu won ni ohun didun, ohun won si
dun pelu,
A! ki awa le se ‘bi ti won lati sin Oluwa,
ff Mimo, Mimo l‘awon angeli nko,
Mo si ni ‘reti lati ba won korin li orun,
cr Sugbon won ko leba mi korin ti irapada
N‘tori angeli ko mo ayo ti ‘gbala mu wa.

2 mf Sugbon mo gbo orin miran ti a ko


l‘ohun oke
Si eni t‘O ra wa pada t‘O si gba wa,
l‘orin na;
f Awa ti la iponju wa ja si ile didan yi,
Nibi orisun ‘ye ti nsan l‘O ti fo aso wa
mo

3 di Awon angeli dake, n‘tori won ko le korin


na,
f Bi iro omi pupo l‘enu awon t‘a f‘eje ra!
N‘tori won nso ti isegun lori ‘danwo
at‘ija‖.
ff Won si nyin Olurapada ti O ti wipe,
―O seun‖.

4 f Bi emi ko tile nse angeli, mo mo pe


l‘ohun
Un o b‘awon mimo korin t‘awon angeli
ko ni ko:
ff Un o korin ti Olugbala ti O ku ni Kalfari
Lati dari ese mi ji mi, lati da mi sile. Amin.

956 15.15.15.14 & Ref


Osi fi ilu nla ni han mi Jerusalemu mimo
Ifi. 21:10.

1 Ile alafia kan wa, ti ‗lekun re si s‘ile,


Eni ti okan re funfun, ti o si mo,
y‗o gbe ‗be;
K‘ise enu ona ogo nikan l‘a ni ba wo le
cr Sugbon eni ti y‘o WO ‘be yo k‘ese sile na
di Wa nihin, wa nihin si‘ le eletu loju.
Ko s‘ohun t‘ale fi we adun mimo ti
O wa nibe
mf Wa nihin, wa nihin, fi asale yi sile;
Si jade wa, jade wa.

2 Irugbin orun nhu nibe, ni ‘le re ti o l‘ora,


mf O si nhu igi ajara ti o ntu okan lara;
Oke giga, didan wa n‘be t‘o je ibi itura,
Abo t‘o daju ni o je f‘okan sunmo O

3 cr Tani ko fe lo s‘ile na t‘o fe joko s‘asale


‘Gbati eso ile na pon, ti ‘be si wa nitosi?
mf Nje fi ayo WO ile, n‘tori Oluwa mbe fun O
Niwaju ‘te ogo Re, ni ‘WO O ma gbe titi. Amin.

957 7.6.7.6.& Ref.


O ti pese ilu nla kan sile fun won.
Heb. 11:16.

1 cr Ni ‘le ti ojo ki nsu


N‘ilu Olorun wa;
Ilu na y‘o wa titi,
Ko si s‘oru nibe
mf Baba y‘o n‘omije nu,
Ko s‘iku, ‘rora eru
Ko si kika akoko
‘Tori ko s‘oru n‘be.

2 mf Enu ona re je Pearl,


N‘ilu Olorun wa;
Ita re si je wura.
Ko s‘oru nibe.

3 A ki nti enu ona


T‘ilu Olorun wa;
Omije ‘ye nsan nibe,
Ko si s‘oru nibe.

4 cr Won ko fe ‘tansan orun


N‘ilu Olorun wa;
f N‘tori krist‘ n‘imole re,
Ko si s‘oru nibe
Amin.

958 11.11.11.11.
Eni ti o ba segun ni yio jogun nkan wonyi.
Ifi. 21:7.

1 Ile ewa wonni, b‘o ti dara to!


Ibugbe Olorun, t‘oju ko ti ri;
Tal‘ o fe de ibe, leyin aye yi?
Tal‘ o fe k‘a wo on ni aso funfun?

2 p Awon wonni t‘o ji ninu orun won,


Awon t‘o ni ‘gbagbo si nkan t‘a ko ri:
Awon t‘o k‘aniyan won l‘Olugbala,
Awon ti ko tiju agbelebu Krist‘.

3 cr Awon ti ko nani gbogbo nkan aye,


Awon t‘o le soto de oju iku.
Awon t‘o nrubo ife l‘ojojumo,
Awon t‘a f‘igbala Jesu rapada.

4 f Itiju ni fun yin, Om‘ogun Jesu,


Eyin ara ilu ibugbe orun,
Kinla! e nfi fere at‘ilu sire
‘Gbat‘ o ni k‘e sise, t‘o si pe, ―E ja!‖

5 cr B‘igbi omi aye si ti nkolu wa,


Jesu, Oba Ogo, si si wa l‘eti;
Adun t‘o wa l‘orun ilu mimo ni,
Nibit‘ isimi wa, lae ati laelae.
Amin

959 6.6.6.D.
Ninu ile Baba mi opolopo ibugbe lo wa.
Jn. 14:2.

1 mf Ile ‘bukun kan wa,


Leyin aye wa yi,
Wahala, irora,
At‘ekun ki de ‘be
cr Igbagbo y‘o d‘opin,
Ao de‘reti l‘ade,
f Imole ailopin
Ni gbogbo ibe je

2 mf Ile kan si tun mbe


Ile alafia
cr Awon Angeli rere
Nkorin n‘nu re laelae;
ff Yi‘te ogo Re ka
L‘awon egbe mimo
Nwole, won nteriba
F‘eni Metalokan.

3 mf Ayo won ti po to;


p Awon t‘o ri Jesu,
cr Nibit‘o gbe gunwa,
T‘a si nfi ogo fun,
f Won nkorin iyin Re;
Ati t‘isegun Re;
Won ko dekun royin
Ohun nla t‘o ti se.

4 mf W‘oke, eyin mimo,


E le iberu lo,
p Ona hiha kan na
L‘Olugbala ti gba;
cr E fi suru duro
Fun igba die sa;
f T‘erin-t‘erin l‘On o
Fi gba yin s‘odo Re
Amin.

960 L.M.
Baba, emife ki a won ti iwo fifun mi,
ki o wa lodo mi, nibiti emi gbe wa.
Jn. 17:24.

1 mf Jeki‘m‘ni‘po mi l‘odo Re
Jesu Iwo isimi mi;
‘Gbana l‘okan mi y‘o simi,
ff Y‘o si ri ekun ‘bukun gba.

2 mf Jeki ‘nr ni ‘po mi l‘odo Re,


K‘emi k‘o le ri ogo Re,
‘Gbana ni okan etan mi
Yoo ri eni f‘ara le.

3 mf Jeki‘m‘ni‘po mi l‘odo Re
Nibi awon mimo nyin O
‘Gbana ni okan ese mi,
Y‘o dekun ese ni dida.
4 mf Jeki‘m‘ ni ‘po l‘odo Re.
Nibi a ki y‘ipo pada
Nib‘a ko npe ―o digbose‖
ff Titi aye titi aye.
Amin.

961 L.M.
A wa ti ni Olori Alufa nla kan ti o ti
Koja lo sinu awon orun.
Heb. 4:14.

1 f Olor‘ Alufa giga kan,


T‘o gb‘eda wa WO f‘ara han
Nibi ti tempil orun wa,
Ile ti a ko f‘owo ko.

2 p On bi Onigbowo eniyan
T‘o t‘eje ‘yebiye s‘ile
T‘o npari 'se nla Re l'orun;
Olugbala, Ore eniyan

3 mf B‘o tile g‘oke lo s'orun


O nf‘oju ife wo aye
Eni t‘Oje oko eniyan
O mo ailera eda wa.

4 mp Alabajiya wa si mo
Bi ‘rora wa si ti po to,
di L‘orun, O si ranti sibe
pp Omije on ‘waya ‗ja Re

5 mp Ninu ibanuje okan,


Eni ‘banuje pin n‘nu Re
cr O mba wa daro edun wa
O si nran ojiya lowo

6 f K‘a k‘edun wa lo s‘odo Re


Pelu ‘gboya, nibi ite
K‘a toro agbara orun;
Lati yo wa nigba ibi
Amin.

962 C.M.
O si fi ilu nla han mi Jerusalemu mimo
Ifi. 21 10.

1 Jerusalemu, Ibi ayo,


T‘o se owon fun mi,
‘Gbawo n‘ise mi o pari
L‘ayo l‘alafia?

2 mf ‘Gbawo ni oju mi y‘o ri


Enu 'bode pearl re?
Odi Re t ‘o le fun ‘gbala,
Ita wura didun

3 Ogba ti o ju Eden lo,


Ibi ko si ni be;
Ilu ayo, mo nlepa re
Larin iji aye.

4 mf Ese t‘emi o ko iya.


Iku ati iponju
f Mo nwo ile rere Kenan‘
Ile mole titi.

5 Aposteli, martyr, woli


Won y‘Olugbala ka;
Awa tikarawa fere
Dapo mo ogun na.

6 mf Jerusalem, ilu ayo,


Okan mi nfa si o;
cr ‘Gbati mo ba ri ayo re,
Ise mi y‘o pari.
Amin.

963 6.6.6.6.8.8.
Sugbon nisisiyi won nfe ilu kan ti
O dara ju belo. Heb. 11:16.

1 mf Jerusalem‘ t‘orun
L‘orin mi, ilu mi!
Ile mi bi mba ku;
Ekun ibukun mi;
Ibi ayo!
Nigbawo ni
U n o r‘oju Re
Olorun mi?

2 mf Nibe l‘Oba mi wa,


p T‘a da l‘ebi l‘aye;
f Angeli nkorin fun,
Won si nteriba fun.

3 Patriark igbani,
Par‘ayo won nibe
Awon woli, won nwo,
Omo Alade won!
4 mf Nibe ni mo le ri
Awon Aposteli;
At‘awon akorin
Ti nlu harpu wura

5 mp Ni agbala wonni,
Ni awon Martir wa;
cr Won wo aso ala,
Ogo bo ogbe won.

6p T‘emi yi sa su mi,
Ti mo ngb‘ago Kedar;
Ko si ‘ru yi loke,
Nibe ni mo fe lo
Amin.

964 6.4.6.4.6.7.6.4.
A wa si nlo si ibiti Oluwa wipe emi o fi fun
yin Iwo ba wa kalo.
Num. 10:29.

1 mf Ile ayo kan wa


Ti o jina;
Ni b‘awon mimo wa,
Won nran b‘orun;
A! won nkorin didun
Yiye l‘Olugbala wa
Ki iyin Re ko ro,
Yin, yin laelae.

2 mf Wa sile ayo yi,


Wa, wa k‘a lo,
E se nsiyemeji?
E se nduro?
Ao wa l‘Alafia
Kuro l‘ese at‘aro,
A o ba O joba,
L‘ayo laelae.

3 f Oju gbogbo won ndan


N‘ile ayo,
N‘ipamo Baba wa,
Ife ki ku.
Nje sure lo s‘ogo
Gba ade at‘ijoba
T‘o mo ju orun lo,
Joba titi.
Amin.
965 D.S.M.
Beli awa o si wa lae lodo Oluwa
I Tes. 4:17.

1 mf ―Lae lodo Oluwa,‖


Amin, beni kori,
cr Iye wa ninu oro na,
Aiku ni titi lae
mp Nihin ninu ara
Mo s‘ako jina s‘l
cr Sibe alale ni mo nfi
Ojo kan sunmo ‘le.

2 mf Ile Baba l‘oke


Ile okan mi ni:
Emi nfi oju igbagbo
Wo ‘bode wura re!
p Okan mi nfa pupo
S‘ile na ti mo fe
cr Ile didan, t‘awon mimo,
Jerusalemu t‘orun.

3 di Awosanma dide,
Gbogbo ero mi pin;
Bi adaba Noa, mo nfo
Larin iji lile
cr Sugbon sanma kuro,
Iji si rekoja
Ayo ati alafia
Si gba okan mi kan.

4 mf L'oro ati l‘ale,


L‘osan ati l‘oru
Mo ngbo orin orun bori
Rudurudu aye;
ff Oro ajinde ni,
Hiho isegun ni;
Lekan si, lae l‘od‘Oluwa,
Amin, beni k‘o ri.
Amin.

966 C.M. & Ref.


Mo ni ife lati lo ki emi wa lodo Kristi.
Fili. 1:23.

1 f Paradise; paradise,
Tani ko fe ‘simi,
Tani ko fe ‘le ayo na
Ile alabukun.
Ni b‘awon olotp
Wa lae ninu ‘mole
Won nyo nigbagbogbo
Niwaju Olorun.

2 f Paradise! Paradise!
p Aye ndarugbo lo.
Tani ko si fe lo simi,
Nib‘ife ki tutu.

3 f Paradise! Paradise
p Mo fe ki nye d‘ese
Mo fe ki nwa lodo Jesu
Li ebute mimo.

4 f Paradise! Paradise!
Un ko ni duro pe mo
Nisiyi b‘enipe mo ngbo
Ohun orin orun.

5 f Jesu Oba Paradise


Pa mi mo n‘nu ‗fe Re;
Mu mi de ile ayo na,
Nib‘isimi l‘oke.
Amin

967 8.9.8.H.
Nitori ti o pese ilu kan sile fun won
Heb. 11:16.

1 mf A nsoro ile ‘bukun ni,


Ile didan at‘ile ewa;
‘Gbagbogbo l‘a nso t‘ogo re
p Y‘o ti dun to lati de be!

2 mf A nsoro ita wura Re;


Oso odi re ti ko l‘egbe
‘Faji re ko se f‘enu so;
p Y‘o ti dun to lati de'be!

3 f A nso p‘ese ko si nibe!


Ko s‘aniyan at‘ibanuje,
Pelu 'danwo l'ode, ninu;
p Y‘o ti dun to lati de ‗be!

4 f A nsoro orin Iyin re.


Ti a kole l‘orin aye we,
di B‘o ti wu k'orin wa dun to
p Y‘o ti dun to lati de‘be!

5 f A nsoro isin ife re


Ti agbada t‘awon mimo nwo,
Ijo akobi ti oke;
p Y‘o ti dun to lati de‘be

6 mp Oluwa l‘onakona,
Sa se emi wa ye fun orun:
cr Laipe awa na yio mo
B‘o ti dun to lati de ‘be.
Amin.

968 7.6.7.6.
Awa ko ni ilu ti o duro pe nihin awa
nwa okan ti mbe.
Heb. 13:14.

1 p Kukuru l‘ojaye wa,


Die l‘ojo aro;
cr Aye ti ko lopin mbe
Nibit‘ ekun ko si.

2 mf A! ere wo lo to yi
Isimi ailopin,
At‘ile nla t‘o dara
F‘elese bi awa.

3 cr L‘aye yi awa njagun,


Lorun, ao d‘ade,
Ade ti ki dibaje,
Ti yo ma dan titi.

4 mf Nibe l‘awa o gbe ri


Eni t‘a gbekele,
Iye awon t‘o ba mo
Ni yio je tire

5 cr Owuro ojo na mbe,


Okunkun y‘o ka lo,
f Awon olokan pipe,
Y‘o ma ran bi orun.

6 ff Olorun at‘ipin wa,


N‘nu ekun ore re,
Nibe ni ao ma wo O,
Ao yin lojukoju.
Amin.

969 8.8.6.D.
A wa nyo ni ireti ogo Olorun.
Rom. 5:2
1 mp Leyin aye buburu yi,
p Aye ekun on osi yi,
Ibi rere kan wa;
Ayipada ko si nibe,
Ko s‘oru, a f‘osan titi, ‘
p Wi mi, ‘wo o wa nibe?

2 mf ‘Lekun ogo re ti m‘ese,


Ohun eri ko le wo ‘be,
Lati b‘ewa re je;
f L‘ebute daradara ni,
A ko ni gburo egun mo.
Wi mi, ‘wo o wa nibe

3f Tan‘ y‘o de ‘be? Onirele,


T‘o f‘iberu sin Oluwa,
T‘won ko naani aye:
Awon t‘a f‘Emi mimo to
Awon t‘o nrin l‘ona tooro,
f Awon ni o wa nibe.
Amin.

970 8.9.9.9.& Ref.


Ile rere na ti mbe loke Jordani.
Deut. 3:25.

1 mf A! Ro ti ibugbe orun,
Li eba odo ti imole,
Nibit‘ awon mimo wa laiku
Ti a wo won li aso funfun,
Lok‘orun! lok‘oruri)2ce
A! ro ti ibugbe orun

2 mf A! ro t‘awon ore nibe,


Awon ti o ti lo saju wa
Ati awon orin ti won nko
N‘ile won ni afin Olorun
Lok‘orun! lok‘orun)2ce
A! ro t‘awon ore nibe

3 Olugbala mi wa nibe,
N‘be l‘awon ibatan mi nsimi,
Je ki nfi ‘banuje s‘apakan
Ki nsi fo lo s‘ile abukun.
Lok‘ orun! lok‘orun)2ce
Olugbala mi wa nibe

4 mf Mo fere de ibugbe na,


Nitori mo r‘opin ajo mi,
Opo l‘awon ti okan mi nfe
Won ns‘ona, won si duro demi
Lok‘orun! lok‘orun)2ce
Mo fere de ibugbe na
Amin.

971 8.6.8.6.7.7.7.6.
Nitori Odo-Agutan ti mbe larin ite na ni
yio si ma se amona won si ibi orisun omi iye.
lfi. 7:17.

1 mf A o pade ‘oke odo,


Nigbose, nigbose,
Okunkun y‘o si rekoja
Nigbose, nigbose,
cr ‘Gbati ajo ba pari,
T‘a si segun t‘o logo.
A o si ma ran bi orun
Nigbose, nigbose.

2 f A o ma lu harpu ogo
Nigbose, nigbose.
A o ma korin irapada,
Nigbose, nigbose
cr Titi lae li orin na
Y‘o ma f‘adun ro yi ka
Ebute ayeraye,
Nigbose, nigbose.

3 f Awa y‘o si dabi Jesu,


Nigbose, nigbose
Ti y‘o fun wa l‘ade iye,
Nigbose, nigbose
cr Awon angeli pelu
Ti nmu gbogbo ‘fe Re se
Won y‘o ma se ike wa
Nigbose, nigbose.

4 f Omije oju wa y‘o gbe,


Nigbose, nigbose,
Pelu ayo nla l‘ao si mo,
Nigbose nigbose,
di Awon mimo,t‘o saju
Lo si ile ayo na,
Pe l‘ayo lao tun dapo
Nigbose, nigbose.
Amin.

972 6.6.6.6.8.8.
Okan mi nfa nitoto fun agbala Oluwa.
OD. 84:2.s
1 mf Oluwa wa orun!
Ago Re l‘aye yi,
Ibugbe ife Re,
Ewa Re ti po to!
ff Okan mi n fa s‘ibugbe Re,
O ns'aferi Olorun mi

2 mf Ayo b‘awon ti n sin,


Nibit‘ Olorun yan,
Ti nwon npara ibe
Lati ma josin won
ff Won nyin O sa; ayo b‘awon
T‘o fe ona oke Sion

3 f Lati ipa de‘pa


L‘aye osi wa yi;
Titi won fi goke,
Ti won si yo s‘orun
ff ‘Bugbe Ogo! ‘gba t‘ Olorun
Bam‘ese wa de ibe na.

4 mf Olorun l‘asa wa,


Imole at‘odi.
Owo re kun f‘ebun
A ngba ‘bukun nibe
ff Oun y‘o febun Ore-ofe
Ati ogo fun iran wa.
Amin

973 10.10.10.10.
Isimi kan ku fun awon eniyan Olorun
Heb. 4:9.

1 mf Kini ‘simi ayo; ailopin ni


T‘awon angel at‘awon mimo ni?
mp ‘Simi f‘alare, f‘awon asegun,
f Nibe l‘Olorun je ohun gbogbo

2 mf Tal‘Oba na, tani yi ‘te Re ka?


p Irora itura Re ha ti ri?
mf So fun ni, eyin ti njosin nibe
B‘ahon le so titobi ayo na

3 Jerusalem toto ilu mimo,


T‘alafia re j‘ayo ailopin,
Ar‘ohun t‘a nfe n‘nu re, ka to wi,
A si rigba ju eyit‘ a nfe lo

4 L‘agbara Oba wa, wahala tan,


Laiberu, l‘a o ma korin Sion
Oluwa; niwaju Re, l‘ao ma fi
Idahun ‘fe han f‘ebun ife Re

5 cr 'Simi ko le tele, ‘simi nibe


Enikan ni ‘simi ti nw‘ oju re,
f Nibe, orin Jubeli ko le tan;
mp T‘awon mimo at‘angeli y‘o ko.

6 cr L‘aye yi, pelu ‘gbagbo at‘adua


L‘ao ma s‘aferi ‘le Baba orun
f Bi igbekun ti nti Babiloni
mp Pada lo si ilu Jerusalem.

7 p Nisiyi, a wole niwaju Re.


cr Ti Eni ti ohun gbogbo ise
mf Ninu eni ti Baba at‘Omo
Ati Emi je okansoso.
Amin.

974 7.7.6. & Ref.


A gbo kan ati Oluso agutan kan ni yoo si je.
Jn. 10:16.

1 mf Nihin l‘awa nje ‘rora


Nihin ni a ma pinya,
mp L‘orun ko si ‘pinya
f A! bi o ti dun to!
Dun to, dun to, dun to!
A! bi o ti dun to
Nigbat‘a kio pinya mo!

2 mf Awon t‘o feran Jesu.


Won o lo s‘oke orun.
Lo b‘awon t‘o ti lo

3 mf Omode y‘o wa nibe,


T‘o wa Olorun l‘aye
Ni gbogbo ‘le eko

4 mf Oluko, baba, iya,


Won o pade nibe na,
Won ki o pinya mo.

5 ff Bi a o ti yo po to!
‘Gbat‘ a ba r‘olugbala
Ni ori ite Re!

6 Nibe l‘ao korin ayo,


Titi aye ailopin,
L‘a o ma yin Jesu.
Amin.

975 8.7.8.7 & Ref.


Odo omi iye mimo, o mo gara bi Krista
Ifi. 22:1.

1 mf A o pade l‘eti odo


T‘ese angeli ti te;
T‘o mo gara bi Kristali
L‘eba ite Olorun.
f A o pade l‘eti odo
Odo didan; odo didan na,
Pel‘awon mimo l‘eba odo
T‘o nsan l‘eba ite ni.

2 mf L‘eti bebe odo na yi


Pel‘Olus‘agutan wa,
A o ma rin a o ma sin
B‘a ti ntele ‘pase Re

3 cr Nje l‘eba odo tutu na,


Ao r‘oju Olugbala;
Emi wa ki o pinya mo
Yio korin ogo Re

4 p K‘a to de odo didan na,


A o s‘eru wa kale;
cr Jesu y‘o gba eru ese
Awon ti O de l‘ade.

5 A fe de odo didan na,


‘Rin-ajo wa fere pin;
Okan wa fere kun f‘orin
Ayo at‘Alafia.
Amin.

976 8.7.8.7.8.7.
Jerusalemu mimo, ti nti orun sokale lati
odo Olorun wa.
Ifi. 21:10.

1 f Salem t‘orun, ilu ‘bukun


T‘o kun fun ‘fe at‘ayo,
Ti a f‘okuta aye ko
Ni orun giga loke;
Pel‘ogun angeli yika
T‘o nsokale b‘iyawo.

2 Lat‘ode orun lohun wa


L‘o ti wo aso ogo
T‘o ye Eni ti o fe o;
A o sin o f‘oko re;
Gbogbo ita, at‘odi Re
Je kiki oso wura.

3 Ilekun re dan fun Pearl,


Won wa ni sisi titi;
Awon oloto nwo ‘nu re
Nip‘ ejo Olugbala,
Awon t‘o farada ‘ponju
‘Tori oruko Jesu.

4 Wahala at‘iponju nla


Le s‘okuta re l‘ewa;
Jesu papa l‘Eni to won
Si ipo ti o dara
Ife inu Re sa ni pe
K‘ale s‘afin Re l‘oso

5 ff Ogo at‘ola fun Baba


Ogo at‘ola f‘Omo,
Ogo at‘ola fun Emi
Metalokan titi lae
At‘ayeraye okan na,
Bakan na titi aye.
Amin.

977 8.7.8.7.7.7.
A won Ologbon yio si ma tan bi imole
ofurufu. Dan. 12:3.

1 f Tal‘awon wonyi b‘irawo


Niwaju ite mimo,
Ti won si de ade wura,
Egbe ogo wo l‘eyi?
ff Gbo won nko Aleluya!
Orin iyin Oba won.

2 mf Tali awon ti nko‘ mana


T‘a wo l‘aso ododo?
Awon ti aso funfun won
Yio ma funfun laelae,
Beni ki y‘o gbo laelae,
Nibo l‘egbe yi ti wa?

3 p Awon wonyi l‘o ti jagun


F‘ola Olugbala won;
Won jijakadi tit‘iku,
Won ki b‘elese k‘egbe
cr Wonyi ni ko sa f‘ogun,
f Won segun nipa Kristi.

4 p Wonyi lokan won ti gbogbe


Ninu ‘danwo kikoro
Wonyi li o ti f‘adura
Mu Olorun gbo ti won;
cr Nisisiyi won segun;
Olorun re won l‘ekun.

5 mf Awon wonyi l‘o ti wa,


Ti won file won fun Krist‘;
Won si y‘ara won si mimo
Lati sin nigbagbogbo;
Nisisiyi li orun,
Won wa l‘ayo l‘odo Re
Amin.

978 C.M.
Idile kan li orun ati li aiye.
Efe. 3:15.

1 f Wa, k‘a da m‘awon ore wa


Ti won ti jere na;
N‘ife k‘a f‘okan ba won lo
S‘ode orun l‘ohun.

2 K‘awon t‘aye, d‘orin won mo


T‘awon t‘o lo s‘ogo,
Awa l‘aye, awon l‘orun
Okan ni gbogbo wa.

3 mp Idile kan n‘nu Krist‘, ni wa,


Ijo kan l‘a si je;
di Isan omi kan l‘o ya wa!
p Isan omi iku

4 f Egbe ogun kan t‘Olorun,


Ase Re l‘a si nse;
mp Apakan ti wo ‗do na ja,
Apakan nwo lowo!

5 cr Emi wa fere dapo na,


Y‘o gb‘ade bi ti won;
f A o yo s‘ami Balogun wa
Lati gbo ipe Re

6 cr Jesu, so wa, s‘amona wa


‗Gbat‘ oniko ba de
f Oluwa pin omi meji,
Mu wa gunle l‘ayo
Amin

979 8.7.8.7.
Oluwa mo awon ti ise Tire.
II Tim. 2:19.

1 mf Oba awon eni mimo


T‘o mo ‘ye awon ‘rawo;
Opo eni t‘eda gbagbe
Wa yika ite Re lae.

2 mf ‘Mole ti kuku aye bo


Ntan ‘mole roro l‘oke
Won je Om-alade l‘orun,
Eda gbagbe won l‘aye.

3 mf Lala at‘iya won fun O,


Eda ko r‘oyin re mo;
Iwa rere won f‘ara sin,
Oluwa nikan l‘O mo.

4 di Won f‘ara sin fun wa sugbon


A ki won s‘iwe iye;
Igbagbo, adura, suru,
Lala on ‘jakadi Won.

5 mf Won mo isura Re l‘ohun;


Ka wa mo won, Oluwa,
Nigbat‘O ba nsiro oso,
Ti mbe l‘ara ade Re.
Amin.

980 11.10.11.10.9.11.
Angeli Oluwa wipe lo so gbogbo oro ipe yi.
Ise A. 5:20.

1 mf Gbo, okan mi, bi angeli ti nkorin


Yika orun ati yika aye;
E gbo bi oro orin won ti dun to!
Ti nso‘gbati ese ki o si mo;
p Angeli Jesu, angel‘ ‘mole,
Won nkorin ayo pade ero l‘ona,

2 f B‘asi ti nlo, be l‘a si n gbo orin won:


p Wa, alare, Jesu l‘o ni k‘e wa:
cr L‘okunkun ni a ngbo orin didun won
mp Ohun orin won ni f‘ona han wa.

3 p Ohun Jesu ni a ngbo l‘ona rere,


Ohun na ndun b‘agogo y‘aye ka;
cr Egbegberun awon t‘o gbo ni si mbo,
Mu won w‘odo Re, Olugbala wa.

4 mf Isimi de, bi wahala tile po,


Ile y‘o mo, l‘eyin okun aye;
cr lrin ajo pari f‘awpn alare,
Won o d‘orun ‘bi ‘simi nikeyin.

5 f Ma korin nso, eyin angeli rere,


E ma korin didun k‘a ba ma gbo
cr Tit‘ao fi nu omije oju wa nu
Ti a o si ma yo titi laelae.
Amin

981 7.7.7.D.
E wo iru ife ti Baba fi fe wa, ti a fi npe wa
ni omo Olorun. I Jn. 3:1.

1 f Alabukun n‘nu Jesu,


Ni awon om‘Olorun
Ti a fi eje Re ra
p Lat‘inu iku s‘iye;
cr Ope, a ka wa mo won,
L‘aye yi, ati l‘orun.

2 f K‘a to d‘aye ni Baba


Fe won ninu Omo Re;
Nipa ‘gbagbo n‘nu Jesu
Ni won gba edidi yi.

3 f Awon ti a da l‘are
Nipa ore ofe Re.
A we gbogbo ese won,
Won o bo l‘ojo ‘dajo.

4 mp Won ns‘eso ore-ofe


Ninu ise ododo,
Irira l‘ese si won,
Or‘Olorun ngbe ‘nu won.

5 Nipa ej‘Odagutan,
Won mba Olorun k‘egbe
Pelu olanla Jesu.
A wo won l‘aso ogo.
Amin

982 D.C.M.
Gbogbo awon angeli si duro yi ite na.
Ifi. 7:11.
1 f Baba, niwaju ite Re;
L‘angeli nteriba;
Nigbagbogbo niwaju Re
Ni won korin iyin;
di Won si nfi ade wura won
Lele yi ‘te na ka;
cr Won nfi ohun pelu duru
Korin si Oluwa.

2 mf Didan osumare si ntan


Si ara lye won;
cr Serafu nke si Serafu
Ti won nkorin ‘yin Ite;
p Bi a ti kunle nihinyi
Ran ore Re si wa,
K‘a mo pe ‘wo wa nitosi
Lati da wa lohun

3 mf Nihin, nibit‘awon angel‘


Nwo wa b‘a ti nsin O
cr Ko wa, k‘a wa ile orun,
K‘a sin O bi ti won;
f K‘a ba won ko orin iyin.
K‘a ba won mo ‘ fe Re:
Titi agbara y‘o fi di
Tire, Tire nikan.
Amin.

983 C.M
Mo si gbo ohun awon angeli pupo yi ite na ka.
Ifi. 5:11.

1 f Ewa, k‘a da orin wa po


Mo t‘awon angeli;
Egbegberun ni ohun won
Okan ni ayo won.

2 Won nkorin, pe, Ola nla ye


Od‘agutan t‘a pa;
K‘a gberin pe, Ola nla ye‖
p N‘tori O ku fun wa.

3 mf Jesu li o ye lati gba


Ola at‘agbara;
cr K‘iyin t‘enu wa ko le gba
Je Tire, Oluwa.

4 f K‘awon t‘o wal‘oke orun


At‘ile at‘okun
Dapo lati gb‘ogo Re ga,
Jumo yin Ola Re.

5 ff Ki gbogbo eda d‘ohun po,


Lati yin oruko
Eni t‘O joko l‘or‘ite,
Ki won si wole fun.
Amin

984 7.7.7.6
Kristi feran ijo Re O si
O si fi ara Re fun u. Efe. 5:25.

1 mf Jesu, ba ijo Re gbe,


S‘amona at‘odi re,
B‘o ti nla ‘danwo koja
Awa mbe O, gbo wa.

2 mf F‘owo ife Re yi ka;


Dabobo l‘owo ota,
Tu ninu nigba ibi,
p Awa mbe O gbo wa.

3 mf M‘eko at‘iwa re mo
Je k‘o fi suru duro;
K‘o simi le ‘leri Re,
Awa mbe O, gbo wa.

4 mf Pelu re l‘ojo gbogbo,


K‘o bo lowo isina,
K‘o ma sise fun ‘yin Re,
Awa mbe O, gbo wa.

5 cr K‘ohun re ma ja goro
N‘ikilo ‘dajo ti mbe;
Ni sise ife Jesu,
p Awa mbe O, gbo wa.

6 mf Wa tun ibaje re se,


Wa tun Tempili Re ko;
Fi ara Re han nibe,
p Awa mbe O, gbo wa.

7 cr Wa da gbogbo ide re,


Mu ‘lara at‘ija tan;
M‘alafia orun wa,
p Awa mbe O, gbo wa.

8 mf Mu gbogbo ona re to,


Ma je k‘owo esu te
Ki aye ma le tan je,
p Awa mbe O, gbo wa.

9 cr K‘eko re je okan na
N‘nu otito at‘ife;
K‘o fa opo si ‘gbagbo,
p Awa mbe O, gbo wa.

10 mf K‘o ma toju alaini


K‘o si ma wa asako
At‘oni robinuje;
Awa mbe O, gbo wa.

11 mf Ma je k‘ife re tutu,
M‘awon oluso gboya,
S‘agbara y‘agbo Re ka,
Awa mbe O, gbo wa.

12 mf K‘awon alufa ma bo,


Ki won j‘oluso toto .
Lati ma to ijo Re,
p Awa mbe O, gbo wa.

13 mf Ki won se bi won ti nso,


K‘won f‘apere mimo han
Bi asaju agbo Re,
p Awa mbe O, gbo wa.

14 F‘or‘ofe eni t‘O ku,


At‘ife Baba ba gbe;
K‘Emi ma s‘amona re,
p Awa mbe O, gbo wa.

15 mf We gbogbo arun re nu,


L‘eru on ‘yemeji lo;
Mu ‘segun Re de kankan,
Awa mbe O, gbo wa.

16 p Ran ‘lowo nigba awe


cr Tit‘ise re o pari;
f T‘Oko ‘yawo y‘o si de
p Awa mbe O, gbo wa.

17 ff Nigbana k‘o se logo


Ati ni ailabawon,
L‘ewa didan t‘o ye O
Awa nbe O, gbo wa.

18 Mu ye ki on ba le pin
N‘nu aye t‘Iwo npese;
K‘o n‘ibukun nibe lae,
p Awa mbe O, gbo wa.
Amin

985 8.8.8.6. & Ref.


Won nfe ilu kan ti o dara jube lo.
Heb. 11:16.

1 cr L‘ojo kan sa, ti nko le so,


Un o dagbere fun ‘banuje
Un o ba awon angeli gbe,
Ojo, ojo ayo.
mf Ojo ayo (2)
T‘emi y‘o ma ba Jesu gbe
Ojo, ojo ayo.

2 mf L‘ojo kan ‘nu ‘bode didan,


Emi y‘o gbe harpu wura;
Un o wo aso funfun laulau,
Ojo, ojo ayo

3 L‘ojo kan un o r‘Olugbala,


On yio si gba mi mora
Y‘o si ka mi kun ayanfe
Ojo, ojo ayo.

4 mf L‘ojo kan sa emi mo pe


Un o ri awon t‘o ti koja;
Un o mo bi ‘gbesemi ti to
Ojo, ojo ayo
Amin.

986 8.7.8.7.8.7.8.7. & Ref.


Nigbati O ba farahan, a o dabi Re.
I Jn. 3:2.

1 cr Gbat‘ ikuku ba rekoja


T‘ojo titun ba si de;
mf Ti ‘tansan orun farahan
L‘or‘awon isan omi;
T‘a nranti ‘leri Baba wa
N‘nu didan osumare;
A'o mo ‘ra wa ju t‘isiyi
‘Gbat‘ kuku ba koja
f L‘owuro ‘jo didan ni
Ojo t‘o logo julo
A o mo ‘ra wa ju t‘isiyi
‘Gbat‘ ikuku ba koja,
Ao mo bi a ti mo wa
Lae ka ma da nikan rin.
2 mp Nisiyi, a nrin ajo wa
N‘nu aro on isoro;
p Nisiyi, a nse wa nise
Nihin at‘ibi gbogbo;
cr Sugbon ao gb‘ohun Baba wa
Pe, ―E wa, eyin omo‖
L‘owuro ojo didan ni
Gbat‘ ikuku ba koja.

3 f ‘Gbana okan wa y‘o f‘ayo


Yi ite ogo Re ka;
A o ri awon t‘o fe wa
A o mo b‘a ti mo wa
Orin ‘rapada wa l ao ko
Titi lae ati laelae,
‘Gbat‘ isudede ba kuro
T‘ikuku si rekoja.
Amin.

987 7 6.7.6.D
Mo si ri ilu mimo ni, Jerusalemu titun,
Ilu na si je kiki wura
Ifi. 21:2,18.

1 mf Jerusalem ilu mi
Ti wara, oyin nsan
Itunu ni fun okan
Ti nronu nipa re;
f Tani le so ayo nla
Ti nduro de awa
T‘a se ye fun ilu na.
Ilu ogo titi?

2 Won duro loke Sion,


ff Won nkorin ayo nla,
Gbogb‘ aopn ajeriku
At‘awon angeli.
Oluwa mbe larin won;
Ojo tu won lara,
Ilu awon ayanfe.
Ilu ogo julo.

3 Omo Dafidi njoba


ff Ko si aniyan mo;
Iho ayo isegun,
Orin irapada;
Awon asegun pelu
Balogun won dapo
Won wo aso isegun
Titi ayeraye.

4 Ilu alabukunfun,
Ile ayanfe Re;
Ilu opo ibukun
F‘okan ti npongbe re;
Jesu, jowo se wa ye
Fun ilu isimi
Nibiti Iwo, Baba
Ati Emi gbe wa.
Amin

988 7.6.8.6.D.
Iwo si ti if eje Re si irapada
Eniyan si Olorun lati inu eya gbogbo.
Ifi 1:9.

1 mf Egbegberun aimoye,
Won wo aso ala;
Ogun awon t‘a rapada
Won kun ‘bi ‘mole na;
f Ija won pelu ese
At‘iku ti pari;
E s‘ilekun wura sile
Fun awon asegun.

2 ff Iro Aleluya won


Lo gb‘aye, orun kan;
Iro egbegberun harpu
Ndun pe segun de tan;
Ojo t‘as‘eda aye,
T‘a da orile ede,
Ayo nla pa ‘banuje re
Ti a fun ni kikun.

3 f A! ayo t‘a ko le so
Leti bebe Kenan‘:
Idapo nla wo lo to‘yi,
Ibi t‘a ki npinya;
Oju to kun fekun ri
Y‘o tan ‘mole ayo;
Ki y‘o si alaini baba,
Opo ki y‘o si mo.

4 Mu ‘gbala nla Re fun wa,


Od‘agutan t‘apa
Ko ‘ruko awon ayanfe,
Mu‘pa Re k‘o joba;
Wa ife orile ede,
Da onde Re sile;
Wa fi ami ‘leri Re han
Wa, Olugbala wa.
Amin.

989 7.7.7.7.D.
Awon wonyi li o jade lati inu iponju nla.
Ifi. 7:14.

1 mf Tal‘awon yi t‘aso won


Ndan ju orun osan lo?
Asaju omo ‘mole.
T‘o sunmo ‘te Olorun?
Awon yi l‘otijiya,
Nitori Oluwa won,
Ati ninu isin Re;
‘Won l‘o to Kristi leyin.

2 mp Won t‘inu iponju wa,


Won feje Od‘agutan
Fo ‘so won, nipa ‘gbagbp
Eje na ti we ni mo;
cr Nitorina won njosin
Leba ite Eleda;
Olorun si mba won gbe,
Inu Re si yo si won.

3 mf Won ta‘won asegun yo,


Idanwo won ti pari;
Gbogbo ise won koja
Ebi, ongbe, ko si mo;
Oru ko mu won, n‘tori
Owo orun ko de ‘be.
Ilu ‘tura ni won ngbe,
Ibi ‘mole ailopin.

4 Od‘agutan, l‘ori ‘te,


Y‘o ma bo won n‘gbagbogbo,
Y‘o fonje iye bo won.
Y‘o fomi ‘ye fun won mu;
Y‘o pa ‘banuje won re,
Gbogbo aini won y‘o tan
Y‘o nu omije won nu,
Y‘o fife kun okan won.
Amin.

990 C.M
Won si segun re nipa eje Odo-agutan
Na ati nitori oro won
Ifi 12:11
1 mf Mba le f‘iye igbagbo fo
Wo inu ikele,
Ki nri ayo awon mimo,
B‘ogo won ti po to

2 cr Mo bi won, bi won se segun;


Won f‘ohun kan wipe,
Agbara, Od‘agutan ni
Iku Re l‘ayo won

3 W on kiyesi ipase Re,


Itara Re mu won;
Nipa gbigbo t‘Oluwa won,
Won jogun isimi

4 f O to k‘a yin Amona wa,


F‘apere t‘ o fun wa
Bi opo awon eleri
Ti nf‘ona orun han.
Amin

991 8.8.8.D
Nwon simi kuro ninu lala won.
Ifi 14:13

1 mf Awon mimo, lala pari


Won ti ja, won si ti segun
Won ko fe ohun ija mo
Won da won ‗le l‘ese Jesu
cr A! Eyin eni ibukun
p Isimi yin ti daju to!

2 mf Awon mimo, irin pari


Won to kun sure ije mo
Are at‘isubu d‘opin
Ota on eru ko ri mo
cr A! Eyin eni ibukun
p Isimi yin ha ti dun to!

3 mf Awon mimo, ajo pari,


Won ti gun sile ibukun
Iji ko d‘eru ba won mo,
Igbi omi ko nipa mo
cr A! Eyin eni ibukun
p E nsimi n‘ibi alafia

4 Awon mimo, oku won sun


Ninu ile, awon nsona,
cr Titi won yoo fi jinde
Lati fi ayo goke lo!
f A! eni ‗bukun, e korin
Oluwa at‘Oba yin mbo

5 mf Olorun won, ‗Wo l‘a nke pe,


Jesu, bebe fun wa l‘oke
Emi mimo, Oluto wa
p F‘ore-ofe fun wa d‘opin
cr K‘a le b‘awon mimo simi
Ni paradise pelu Re.
Amin.
992
Matha gba a sile re Maria si gbo oro Re
Luk. 10:38 & 39.

1 f Fun wa ni 'le Kristian


Ile ti a nkeko Bibelt
Ile ti a nlepa ‘fe baba
‗Lati 'fe Re F‘ewa de lade
p Olorun Baba wa
Fun wa n'ile Kristian.

2 f Fun wa ni 'le Kristian


Nibiti bale je oloto
Ile to bo lowo asise
Ile ti nyo fun ‗fe at' orin
p Olorun Baba wa
Fun wa ni ‗le Kristian

3 f Fun wa ni 'le Kristian


Nibi t‘iya ile b'ayaba
Nfihan p'ona Re lo dara ju
Ile t'a gb'Olugbala l'aye
p Olorun Baba wa
Fun wa ni ‗le Kristian.

4 f Fun wa ni 'le Kristian


Nibiti anto awon 'mode
Lati mo Kristi to feran won
Ile ti a ntanna adura
p Olorun Baba wa
Fun wa ni 'le Kristian.
Amin.

993
Awon orun nsoro ogo Olorun,
ati ofurufu nfi ise Owo Re han.
OD. 19:1

1p Olorun mi‘gbati mo f‘iyanu wo


Gbogbo aye t'o ti f‘owo Re da
Mo ri ‗rawo, mo gbohun ara ti nsan
Agbara Re han ni gbobgo aye.
mp Okan mi nkorin s'Olugbala mi
Agbara Re ti to tobi to?
Okan mi nkorin s‘Olugbala mi
Agbara Re ti tobi to?

2 p Pelu 'yanu mo wo ‗se Re l‘aginju


Eye nkorin didun lori igi
Mo wo ile lat‘ ori oke giga
Mo r‘agbara odo at‘ afefe

3 p Gbati mo ro b‘Iwo ti fi Omo Re


Sile lati ku, ko tile ye mi
L'ori agbelebu l‘oru ese mi
Eje Re lo ti ki eje mi lo.

4 p Gbati Jesu ba de n‘nu Ola nla Re


Lati pe mi ayo mi yo ti to
Gbana ni 'rele un o wole lati sin
Un o wipe Olorun ti tobi to.
Amin.

994
Ounje mi ni temi emi si ni tire
O Sol. 2:16

1 f O damiloju, mo ni Jesu
Itowo adun orun l'eyi je
Mo di ajogun igbala nla
Eje re we mi, a tun mi bi,
Un o so itan na, un o korin na
Un o yin Olugbala mi titi
Un o SO itan na, un o korin na
Un o yin Olugbala mi titi.

2 Un o teriba fun tayotayo


Mo le ri iran ogo bibo Re
Angeli nmu ihin didun wa
Ti ife at‘anu Re si mi.

3 f Un o teriba fun, un o simi le


Mo di ti Jesu mo d' eni 'bukun .
Un o ma sora, un o si gbadura
Ki ore Re ma fi mi sile.
Amin.

995
Nitoripe bi o wu ki ileri Olorun e to,
ninu Re ni beni ati inu re ni Amin, si ogo
Olorun nipase wa
II Kor. 1:20.

1 mf Mo nduro lori ileri Krist' Oba


Eniti a o ma yin titi laelae
Ogo f‘Olorun, emi yo ma korin
Mo nduro lori ileri Re.
p Emi nduro.................
(Mo nduro de ‘leri, Monduro de ‘leri)
Emi nduro lori ileri Oluwa
Emi nduro ileri nduro
Emi nduro lori ileri Re.

2 mf Mo nduro le ileri ko le ye
Gbati iji 'yemeji at‘ eru ba de
Nipa Oro Re li emi yo segun
Mo nduro lori ileri Re,

3 mf Ileri Re la mi loju lati ri


Iwenumo pipe ninu eje Re
Ileri Re SO okan mi d‘ominira
Mo nduro lori ileri Re.

4 mf Mo nduro le ileri Krist' Oluwa


Ife lo fi so mi po mo ara Re
Nipa oro Re mo nsegun lojojo
Mo nduro lori ileri Re
Amin.

996
E lo si gbogbo aye, ki e si ma wasu
ihinrere fun gbogbo eda
Mk 16:15

1 f To asako lo, lo f‘ife ro won


Awon t' o sina s' ori oke ,
Wa sodo mi! ni ohun Jesu wi
p Gbo b'Oluwa ti mbebe loni.
A nrin ajo lo s' ori oke
Lati pe asako pada (pe pada)
Sinu agbo Olugbala wa
Jesu t‘a pa fun elese (pa f‘elese)

2 f To asako lo, fi Jesu han won


Okan are t‘o si ti gbogbe
Ma sin won lo si ona igbala
Fi ona iye pipe han won.

3f K'a ma te siwaju n'ise rere


K'a ma tele Kristi lojojo
Ka ma se 'anu gb'eni subu ro
K'a ma fi Jesu han asako.
Amin

997
Ko si igbala lodo elomiran nitori ko
Si oruko miran labe orun ti a fi fun ni
ninu eniyan nipa eyiti a le fi gba wa La.
Ie A 4:12
1 f Sa di oruko Jesu mu
N‘igba ibanuje re
Y'O si fi itunu fun o
Ro mo ni ibi gbogbo
Oruko...... Iyebiye
Ireti wa l‘aye yi
Oruko ....... iyebiye
Ayo fun awon t‘orun.

2 f Ma fi oruko Jesu se
Asa nigba idanwo
B'idamu kan ba de ba o
F'oruko na gbadura.

3f Ma iyebiye l'ooko Jesu


O nimu ki okan wa yo,
Gbat' apa 'fe Re ba gba wa.
A o korin iyin Re.

4 mf Ao juba oruko Jesu


Ao wole li ese Re
Ao de Oba wa l'ade
Gbat' tajo wa ba pari.
Amin.

998
Nigbana li a o si gba awa ti o wa laye
ti o si ku lehin soke pelu won sinu
awonsanma
Thess. 4:17

1 f Eje k‘a korin ti y'o da wa laraya


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Ile y‘o su a o si ji si ayeraye
Ko ni pe mo ti a o fi de 'le.
mp Laipe ao de ‘le, laipe ao de 'le
T'awa ti Balogun wa
Ao segun iku, ao pade lai pinya mo
Ko ni pe mo ti ao fi de ‘le

2 f Jek‘a gbiyanju k‘a sise tokan –tokan


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Ore ofe Re o s'agbara wa d'otun
Ko ni po mo ti ao fi d'le

3 E je k'a ran awon alailera lowo


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
K‘a fi ife f‘awon asako s‘odo Re
Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
4 f Isimi daju a o bo lowo aniyan
Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Ko si ekun l'ebute daradara na
Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Amin.
999
E ma sowo titi emi ofide
Luk 19:13

1 mp Un o ha lo ni owo ofo?
Ki nlo pade Jesu be?
Nko iti eise ojo kan fun
Nko iti mu enikan wa.
p Un o ha lo ni owo ofo?
Un o ha pade Jesu be?
Ko si eso kan lowo mi
Ti mo le mu pade Re?

2 mp Iku ko lo nderuba mi
Tori Jesu ti gba mi
Pe mo nlo ni owo ofo
Iro yi mb'okan mi je.

3 mp A! akoko ti mo sonu
Mba le pe won pada bo
Mba fi won fun Oluwa mi
Ife Re ni mo fe se

4 mp Enyin mimo, tara sise


Sise,'gbati se osan
Ki igbe aye yin to pin
So eso fun Oluwa.
Amin
1000
Fa mi lo si Apata ti o ga ju mi lo
OD. 61:2

1 f Mo ntesiwaju l'ona na
Mo ngoke si lojojumo
mp Mo gbadura bi mo ti nlo
Oluwa jo gbe mi soke,
f OluWa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga
Apata t‘o ga ju mi lo
Oluwa jo gbe mi soke.

2 f Ife okan mi ko kuro


Larin 'yemeji at'eru
Awon miran le ma gbe be
Ibi giga l'okan mi nfe

3 f Mo fe ki nga ju aye lo
B'esu tile ngbogun ti mi
Mo nfi gbagbo gbo orin na
Ti awon mimo nko loke.

4 f Mo fe de 'bi giga julo


Ninu ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de be
Oluwa mu mi de 'le na.

5 f Fa mi lo si ibi giga
Laisi Re nko ni le de ‘be
Fa mi titi d' oke orun
Ki nkorin lati ‘ibi giga.
Amin.
ONIRURU

1 12.12.10.11.10.4
Ki Olorun ki o sanu fun wa,
Ki o si busi wa.
OD. 67:1

1 f Bukun ‗le wa at‘ebi wa, at‘ara wa – 2ce


Ibukun orun, iranwo, Re,
mf Ibukun orun ko fi kari awa,
K‘o fi fun wa o, l‘aye l‘orun o,
Baba orun

2 f Tu wa lara, Alagbara, se ‗toju wa, - 2ce


Itunu Re, alafia Re,
mf Ike Re, K‘O fi toju wa, ye,
awa mbe O o, gbo adura wa,
Oba Ogo.

3 f Baba fun wa l‘Emi mimo at‘agbara – 2ce


Iranse orun, ebun lat‘orun
mp Itunu Baba, k‘o wonu okan wa,
K‘o gbe ‗nu wa o, k‘o fun wa l‘ayo,
Oba Orun.

4 mf Awa f‘iyin at‘ope fun Baba l‘orun – 2ce


Iyin fun ‗ranwo, ope fun anu,
f Ayo fun ‗dasi ti a nri lojojo,
Ope fun O o, a tun juba Re,
Baba awa. Amin

2 13.9.8.8.10.6
Gbo oun ebe mi, nigbati mo ba nkigbe pe O
OD 28:2

1 mf Emi y‘o gbadura s‘Oba mi, Edumare,


Baba, ye ko wa gba mi o e;
f Okansoso Ajanaku,
Wa pelu mi, ye Baba o
cr Emi, omo Re, nkepe O o,
Baba, wa duro gbo

2 mf Emi y‘o gbadura s‘Oba mi, Edumare,


Baba, ma fi mi sile o e;
f Ran mi lowo Olubukun,
Wa sike mi nile Re o

3 mf Emi y‘o gbadura s‘Oba mi, Baba rere,


Ma jek‘emi padanu o e;
f Iwo ni Oba aiku
Wa pade mi n‘ile Re o

4 mf Emi y‘o gbadura s‘Oba mi, Edumare


Baba, wa fun mi l‘ere o e;
f Okansoso Ajanaku,
Ye bukun mi n‘ile Re o
Amin.

3 9.9.9.9. & Ref


Emi o ma yo ninu Olorun igbala mi
Hab. 3:18

1 f Okan mi yin Oluwa logo,


Oba iyanu t‘O wa mi ri:
Un o l‘agogo iyin y‘aye ka
Un o si fife Atobiju han
f Oluwa, ope ni fun O
Fun ore-ofe t‘O fi yan mi,
Jowo dimi mu titi dopin
Ki nle joba pelu Re loke

2 mp Bi eranko l‘emi ba segbe


cr Bikose ti Oyigiyigi;
Lairotele l‘Emi Mimo de
f T‘O f‘ede titun si mi l‘enu

3 f Ayo okan mi ko se rohin


Loro, losan, loganjo oru;
Gbat‘ Emi Mimo ti de 'nu mi
Mo nkorin orun lojojumo

4 mf Jesu ti la mi loju emi,


Mo si f‘eti gbohun ijinle
f O nse faji ninu okan mi;
mp Kini mba fi fun Olugbala?

5 f Em‘o sogo ninu Oluwa


K‘emi ma ba di alaimore;
B‘O ti pe mi iyanu l‘o je
Awon angel d'olulufe mi

6 mf Mo damure lati sin Jesu


Lai f‘ota pe larin aye yi;
Nibikibi t'O ba nto mi si
O daju ko ni jeki ndamu

7 mf Bi mba pari ‗re-ije l‘aye,


Olugbala, ma je ki npofo;
Ni wakati na jeki ngbo pe,
Bo sinu ayo ayeraye
Amin

4 Irregular
Adura ki adura tabi ebe ki ebe ti a
ba ti odo enikeni gba, ki IWO ki o si
san fun olukuluku gegebi gbogbo ona re
IIKro. 6:29 & 30.

f Baba, awa yin O o,


Baba, awa yin O o,
Baba, awa f‘irele josin fun O o,
Edumare.

1 Awa dupe pe O da wa si,


A ri owo ibukun Re ni aye wa se,
mf Baba, awa f‘irele josin fun O o,
Edumare.

2 f O seleri irorun ninu ohun gbogbo,


O pese ile ijosin ni akoko yi,
mf Baba, awa f‘irele josin fun O o;
Edumare.

3 mf Aw‘ Omo Re ti O misi o lati seyi fun O,


F‘alafia at‘emi gigun at‘ayo fun wa;
Baba, awa f‘irele josin fun O o,
Edumare.

4 mf Aw‘omo Re ti O misi o lati seyi fun O,


F‘ijoba orun sike wa o nikeyin aye wa;
Baba, awa f‘irele josin fun O o,
Edumare.

5 mf Eyin ogun Orun, sokale, e ya ‘hin si


mimo,
E fi ibere wa fun wa l‘akoko gbogbo;
Baba, awa f‘irele josin fun O o,
Edumare.
Amin.

5 8.6.6.6.7.10.
E korin si Oluwa, fi ibukun fun oruko Re;
e ma fi igbala Re han lati ojo de ojo
OD. 96:2.

1 mf E fi ‘bukun fun Olorun,


Olodumare ni;
Eni t‘O da aye,
At‘ohun inu re,
Fun ike omo eniyan
Iyin, ola at‘ogo f‘Oluwa!

2 f Olubukun at‘Ologbon,
‘WO Ologo l‘a nyin;
Eni t‘O da wa si,
To bukun ise wa,
To si ngbe ori wa ga,
Iyin, Ola at‘ogo f‘Oluwa.

3 mp ‘Gbati ese wa fi wa sun,


p T‘okan wa banuje,
cr Igbe wa ke t‘O lo;
O si gbo ebe na;
f O si da wa ni ide.
Iyin, Ola at‘ogo f‘Oluwa!

4 f Iyin lo ye Kristi Oba;


E de l‘ade pupo;
Eni t‘O fi ife,
‘Mole at‘emi Re
Mu ‘rapada wa s‘aye;
Iyin, OQla at‘ogo f‘Olorun!

5 ff B‘irun mi je kiki ahon,


Ko to fun iyin Re;
B‘Olorun tile ga
Ju gbogbo iyin lo,
Sibe un o korin ope;
Iyin, Ola at‘ogo f‘Oluwa!
Amin

6 11.7.11.7. A Ref.
Awa feran Re nitori On li o ko feran wa.
I Jn. 4:19.

1 f Iwo to le wa la o ma sin titi


Oluwa Olore wa;
Iwo to nso wa n'nu idanwo aye,
Mimo, logo Ola Re,
mf Baba, Iwo l'a o ma sin,
Baba, Iwo l‘a o ma bo,
Iwo to fe wa l'a o ma sin titi,
Mimo l‘ogo Ola Re

2 f Iwo to nsure s‘ohun t‘a gbin s‘aye


T‘aye fi nrohun je o;
Awon to mura lati ma s‘oto,
Won tun nyo n‘nu ise Re

3 ff Iwo to nf‘agan l‘omo to npe ranse


Ninu Ola Re to ga;
Eni t‘o ti s‘alaileso si dupe
Fun ‘se ogo Ola Re.

4 mf Eni t‘ebi npa le ri ayo ninu


Agbara nla Re to ga,
Awon to ti nwoju Re fun anu
Won tun nyo n‘nu ise Re

5 f F‘alafia Re fun ijo Re l‘aye


K‘ore-ofe Re ma ga.
K‘awon eni Tire ko ma yo titi
Ninu ogo ise Re
Amin.

7 10.10.10.10.12.16.16.10.
Nitoriti Oluwa po li ore; anu Re ko nipekun.
OD. 100:5.

1 mf Emi y‘o san ore o f‘Olorun mi)2x


Eni da mi si o latesi wa )2x
Fun jije, fun mimu, t‘o n b‘asiri mi
Fun ipese lojojumo l‘ona ara jaburata
Ko je k‘aye yo mi, loju elegan, aye mi
Dara
f Emi y‘o fore han f‘Olorun mi.

2 E jek‘ asajoyo fope oni)


Eni ba m‘ore Re waka s‘ope )2x
F‘ori wa to dara, ti O nbukun fun wa
O fi‘gbala da wa lola, O npese ohun
gbogbo
Ko jek‘ awa segbe, loju elegan, O gbe
wa ro o
Eni ‘nu re ba dun je ko yo o.

3 f Emi y‘o yin Jesu, Oba Ogo)


Olu seun ara, O m‘ayo mi kun )2x
O da mi lola o, O tun pe mi l‘omo
O f‘ohun atata le mi lowo, ohun ijinle to
daju
Ko jek‘ eru ba mi, loju elegan o ye mi si
o
Emi y‘o yin Jesu, Oba ogo.

4 E je k‘a fope han f‘Olorun wa)


Eni da wa si o d‘ojo oni )2x
O fun wa logbon o, O tun pe wa sagbo
Omo Igbala mura giri, ko ma foya rara
Rara
Duro ninu ‘gbagbo, lojo aye re, a dara
fun o
E jek‘a f ope han f‘Olorun wa.
Amin.

8 11.11.11.12. & Ref


Oro na si di ara, on si mba wa gbe,
(awa si nwo ogo re, ogo bi ti Omo bibi kansoso lati odo) o kun fun ore-ofe ati otito.
Jn. 1:14

f E ba wa yin Oluwa, Aleluya!


Eni ba more Jesu k‘o ba wa gbega,
E ba wa yin Oluwa, Aleluya!
E ni ba more Jesu k‘o ba wa gbega
Eni ba more Re k‘o ba wa gbega
Eni ba more Re k‘o ba wa gbega
E ba wa yin Oluwa, Aleluya!
Eni ba more Jesu k‘o ba wa gbega

1 mf Eni t‘O f‘orun sile t‘O wa s‘aye,


p Lati ku fun ese araye gbogbo;
cr E korin Aleluya s‘Oba mimo
Eni ba more Jesu k‘o ba wa gbega.

2 mf Eni t‘O npa wa mo o, lojojumo,


Eni t‘O nyo wa ninu ewu gbogbo,
Eni t‘Onpa Israeli mo'k‘itogbe;
f Eni ba more Jesu k‘o ba wa gbegu.

3 mf Eni t‘O npese fun aini wa I‘aye,


Eni t‘O nsore fun wa l‘ojo gbogbo,
cr Ore t‘O nse fun wa ko l‘onka rara;
Eni ba more Jesu k‘o ba wa gbega.

9
A bi Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti ise Kristi Oluwa. Lk. 2:11.

1 mf Iyin f‘Eni Mimo,


Iyin f‘Olu agbaye,
Iyin fun Jehofa loke
T‘O f‘Omo iyanu fun wa
cr Ipe ndun l‘orun pe; ―a bi Oba wa.‖
Ogun orun nkorin ogo,
Ogo ni fun Olorun,
E ku ayo Omo, gbogbo eniyan
A bi Jesu Oba.

2 mf Ogo f‘Eni Mimo,


Eleda ohun gbogbo,
Ogo ni fun Olodumare
T‘O ran Messiah w‘aye;
Ipe ndun l‘orun pe: ―a bi Omo Oba,‘
Angeli nkorin pe:
―Alafia fun eniyan‖
E ba wa yo o, gbogbo eniyan
Olugbala wa wa s‘aye.

3 Ise Oluwa, iyanu ni 3x


O gbe‘nu Wundia sola,
O gb‘ona iyanu mu ‘gbala w‘aye ‘
Eniyan sorire, eniyan sorire,
Eleruniyin, O ma se o,
A bi Oba'iyanu
Ipe ndun l‘orun pe: ―a bi Oluwa wa‘
Ogun orun nrin ogo,
Ogo ni fun Olorun;
E ku ayo Omo, gbogbo eniyan
Abi Jesu Oba.
Amin.

10 15.6J5.6.&Ref.
Ijo eniyan nkigbe wipe, Hosanna fun
Omo Dafidi! Olubukun li eniti o mbo wa li
oruko Oluwa! Hosanna loke orun.
Mat. 21:9

1 mf Awon omode s‘eka wewe at‘imope


s‘ona,
f Won si nke, Hosana,
Eyi ni orin ‘segun t‘a ko wonu Jerusalem
ff Hosana! Hosana!
f Eyi l‘Omo nla Dafidi ati Oba Israeli!
O gun ketekete lo fun igbala omo
eniyan,
ff Hosana! Hosana!
Hosana si Omo Dafidi!

2 mp Awon agbagba gbiyanju lati pa won lenu


mo.
f Won tun nke Hosana;
mf B‘awon wonyi pa enu won mo, okuta yo
soro,
f Hosana! Hosana!

3 mf E so fun omobinrin Sion pe


Oba re mbo wa
f Hosana! Hosana!
cr O tenu, O si joko lori omo ketekete,
f Hosana! Hosana!
4 mf Olubukun l‘Eniti mbo wal‘oruko Oluwa!
ff Hosana! Hosana!
mf E te okan yin si ona fun Kristi, Oba Ogo,
f Hosana! Hosana!
Amin.

11 7.5.7.5.6.5.5.4.
Sugbon enyin o gba agbara; nigbati Emi
mimo ba ba leyin.
Ise A. 1:8.

1 mf Emi Baba Alaye,


Sokale pelu
Agbara Pentikosti;
So okan waji,
f Ki O si mu gbona;
B‘ina orun, wa
Pelu ‘tunu nla;
Tan ‘mole re.

2 mp Aye ati emi wa,


Gba, fi se Tire;
Ninu isin wa fun O
Ka ni ‘ranwo Re
Lati j‘olotito;
K‘ebun at‘orun
Ti Pentikosti
Ba s‘ori wa.

3 cr Fi eje ‘yebiye Re
T‘oke Kalfari
We okan ese wa nu;
Si ra wa pada;
Fi ‘fe kun aya wa,
Ka rin ‘na oto
Ife Re lao se
Bi ti orun.

4 mf Baba, Omo on Emi,


Metalokan lae,
f Iyin, ogo, agbara
Je Tire nikan;
Ewa Re l‘aye yi,
Yo je ayo wa
Pelu idupe,
Aleluya!
Amin.

12 11.9.11.9. & Ref.


Emi Oluwa Jehofa mbe lara mi.
Isa. 61:1.

1 mf Ati mu mi l‘aginju aye yi ja


Lori oke ati petele;
Ko si ohun kan t‘o wu mi ninu re,
A fi Jerusalem t‘orun.
f Ojo mbo t‘a o dagbere
Fun aye pe o digbose;
Ojo mbo, ara, ojo mbo
Ti a o lo s‘ile wa loke.

2 mf Mo duro, mo wo ona Jerusalem,


Okan mi npongbe lati de ‘be;
Ohunkohun ti y‘o ba mu ‘dena wa
Metalokan ba mi mu kuro.

3 mf Ojojumo l‘okan ese mi npada


Kuro lodo Jesu Oluwa;
Jowo, Jesu, feje mimo Re ra mi,
F‘Emi Mimo Re to mi sona.

4 mf Aye nti mi sihin, nwon nti mi sohun,


Se, nko ni pada lodo Jesu;
Mo seleri lati ba Jesu joba
Ileri na ko ni tase lae.

5 mf A ti fi ile rere Kenan‘ han mi,


Ewa re ko se fenu royin
Ara, bawo l‘eyin o ha se de ‘be?
Okan ti ko de ‘be padanu.

6 mf Eyin ara, e ba mi yin Oluwa


T‘O fona Aposteli han mi;
L‘ojo oni mo mo Jesu l‘Oba mi,.
O f‘Emi Mimo Re kun ‘nu mi.

7 mf Jesu, jowo di mi mu titi d'opin


Ki nle ba O d‘opin l‘o dun ju.
f Aleluya! e yin Jesu l‘ekan si
Aleluya! l‘orin ikehin!
Amin.

13 6.9.9.9.6.6
Matha gba a sile re Maria si gbo oro Re
Luk. 10:38 & 39.

1 f Fun wa ni 'le Kristian


Ile ti a nkeko Bibelt
Ile ti a nlepa ‘fe baba
‗Lati 'fe Re F‘ewa de lade
p Olorun Baba wa
Fun wa n'ile Kristian.

2 f Fun wa ni 'le Kristian


Nibiti bale je oloto
Ile to bo lowo asise
Ile ti nyo fun ‗fe at' orin
p Olorun Baba wa
Fun wa ni ‗le Kristian

3 f Fun wa ni 'le Kristian


Nibi t‘iya ile b'ayaba
Nfihan p'ona Re lo dara ju
Ile t'a gb'Olugbala l'aye
p Olorun Baba wa
Fun wa ni ‗le Kristian.

4 f Fun wa ni 'le Kristian


Nibiti anto awon 'mode
Lati mo Kristi to feran won
Ile ti a ntanna adura
p Olorun Baba wa
Fun wa ni 'le Kristian.
Amin.

14 12.12.12.11. & Ref.


Nwon o si ma ri oju Re; Oruko Re yo
Si wa ni iwaju
Ifi 22:4

1 mf Ninu irin ajo mi beni mo nkorin


Mo ntoka si Kalfari s‘ibi eje na
Idanwo lode ninu l‘ota gbe dide
Jesu l‘O n to mi lo isegun daju
f A! mo nfe ri Jesu, Ki nma w' oju Re
Ki nma korin titi, nipa ore Re
Ni ilu ogo ni ki gbohun soke
mp Pe mo ho, ija tan, mo de ile mi

2 mf Ninu ise isin mi, b‘okunkun ba su


Un o tubo sunmo Jesu y' O tan imole
Esu le gb‘ ogun ti mi ki nle sa pada
Jesu l‘o nto mi lo, ko s‘ewu fun mi.

3 mf Bi mo tile bo sinu afonifoju


Imole itoni Re y'o mole si mi
Y'o na owo Re si mi, y'O gbe mi soke
Un o tesiwaju b‘O ti nto mi lo.

4 mf Nigbati igbi aye yi ba nyi lu mi


Mo ni abo t'o daju labe apa Re
Y'O ma f‘owo Re to mi titi de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f‘E to
Amin.

15 11.10.11.10. & Ref.


Awon orun nsoro ogo Olorun, ati ofurufu nfi ise
Owo Re han.
OD. 19:1

1p Olorun mi‘gbati mo f‘iyanu wo


Gbogbo aye t'o ti f‘owo Re da
Mo ri ‗rawo, mo gbohun ara ti nsan
Agbara Re han ni gbobgo aye.
mp Okan mi nkorin s'Olugbala mi
Agbara Re ti to tobi to?
Okan mi nkorin s‘Olugbala mi
Agbara Re ti tobi to?

2 p Pelu 'yanu mo wo ‗se Re l‘aginju


Eye nkorin didun lori igi
Mo wo ile lat‘ ori oke giga
Mo r‘agbara odo at‘ afefe

3 p Gbati mo ro b‘Iwo ti fi Omo Re


Sile lati ku, ko tile ye mi
L'ori agbelebu l‘oru ese mi
Eje Re lo ti ki eje mi lo.

4 p Gbati Jesu ba de n‘nu Ola nla Re


Lati pe mi ayo mi yo ti to
Gbana ni 'rele un o wole lati sin
Un o wipe Olorun ti tobi to.
Amin.

16 8.7.8.7.8.8.7 & Ref.


O si mu goke pelu, lati inu iho
Iparun jade wa. OD. 40:2

1 f Okan wa kun fayo loni


A ti r‘ona wura na
Imole re ntan l‘ona wa
A ti r‘ona wura na
O ti pe t'ayun Re nyun wa
Larin ayidayid' aye
Die lo ku fun wa k‘ o bo
K‘ a to r' ona wura na.
Nje korin, korin ayo
F‘okan ayo korin soke
Imole de, a de ‘ile wa
f Ati r'Ona wura na.

2 A pe wa kuro l‘aye yi
A ti r‘ona wura na
Awa jeri pe didun na
K'a ma tase ijoba orun
Pelu Jesu a nlo ‘le wa
f A ti r‘ona wura na.

3 p Kiun ni ‘danwo wa t'o koja


A ti t'ona wura na
Ayo ile mu k'a gbagbe
A ti r'ona wura na
‘Ji kuku ko ni pe kuro
Ifayabale yoo si de
A ta ‘gbokun, oko si gun le
A ti r‘ona wura na.

4 Pel‘okan 'e s‘Olorun wa


A ti r‘ona wura na
Lekan ri ti a ti sonu
A ti r‘ona wura na
A fe d'odo Olugbala
Jesu yoo f‘ayo gba wa
O je nipa or' ofe nikan
A ti r‘ ona wura na.

5 f A dupe l‘ow' Olorun wa


Ti p‘a r'ona wura na
Iyin, ogo ope, ola
Fun Baba ati Omo
Ati pelu Emi Mimo
Metalokan ayera ye
Titi aye lao ma yin;
f Pe a r'ona wura na.
Ope ni fun O Elshadai
Jehofa Rofai ni k‘ayin
Aleluya orin iyin
Fun Metalokan soso
Amin

17 9.10.9.9. & Ref.


Ounje mi ni temi emi si ni tire
O Sol. 2:16

1 f O damiloju, mo ni Jesu
Itowo adun orun l'eyi je
Mo di ajogun igbala nla
Eje re we mi, a tun mi bi,
Un o so itan na, un o korin na
Un o yin Olugbala mi titi
Un o SO itan na, un o korin na
Un o yin Olugbala mi titi.

2 Un o teriba fun tayotayo


Mo le ri iran ogo bibo Re
Angeli nmu ihin didun wa
Ti ife at‘anu Re si mi.

3 f Un o teriba fun, un o simi le


Mo di ti Jesu mo d' eni 'bukun .
Un o ma sora, un o si gbadura
Ki ore Re ma fi mi sile.
Amin.

18 11.1 LI 1.9. & Ref.


Nitoripe bi o wu ki ileri Olorun e to,
ninu Re ni beni ati inu re ni Amin, si ogo
Olorun nipase wa
II Kor. 1:20.

1 mf Mo nduro lori ileri Krist' Oba


Eniti a o ma yin titi laelae
Ogo f‘Olorun, emi yo ma korin
Mo nduro lori ileri Re.
p Emi nduro.................
(Mo nduro de ‘leri, Monduro de ‘leri)
Emi nduro lori ileri Oluwa
Emi nduro ileri nduro
Emi nduro lori ileri Re.

2 mf Mo nduro le ileri ko le ye
Gbati iji 'yemeji at‘ eru ba de
Nipa Oro Re li emi yo segun
Mo nduro lori ileri Re,

3 mf Ileri Re la mi loju lati ri


Iwenumo pipe ninu eje Re
Ileri Re SO okan mi d‘ominira
Mo nduro lori ileri Re.

4 mf Mo nduro le ileri Krist' Oluwa


Ife lo fi so mi po mo ara Re
Nipa oro Re mo nsegun lojojo
Mo nduro lori ileri Re
Amin.

19 7.7.7.7
Nitori oruko Re Oluwa, dari ese mi ji,
nitori ti o tobi - OD.25:11
1 mf Mo ti mb'ese rin ti pe
cr Pin wa n'iya Oluwa
p Ore parun ni tire
pp Gba mi Jesu mo segbe.

2 mf Ko s'anfani ti mo ri
p L'ara ati l‘okan mi
Gbogbo re lo d'ibaje.
pp Jesu gba mi mo segbe

3 mf Mo r'iye nin' oro Re


cr Ibagbe Re si wu mi
p Ese di mi mu sinsin.
pp Gba mi Jesu, jo gba mi.

4 mf O ha dake ki njegbe
Nitori ailera mi
O ha jowo mi fese
p K'a ma ri, Jesu gba mi.

5 Iwo t'O r‘inu r‘ode


lyanju mi han si O
O mo bi mo ti nja to
O r‘omije 'koko mi.

6 Ese fi ewon de mi
Da mi Oluwa da mi
Iwo ni un o sin titi
Jesu Olugbala mi
Amin

20 10.9.10.9. & Ref.


E lo si gbogbo aye, ki e si ma wasu
ihinrere fun gbogbo eda
Mk 16:15

1 f To asako lo, lo f‘ife ro won


Awon t' o sina s' ori oke ,
Wa sodo mi! ni ohun Jesu wi
p Gbo b'Oluwa ti mbebe loni.
A nrin ajo lo s' ori oke
Lati pe asako pada (pe pada)
Sinu agbo Olugbala wa
Jesu t‘a pa fun elese (pa f‘elese)

2 f To asako lo, fi Jesu han won


Okan are t‘o si ti gbogbe
Ma sin won lo si ona igbala
Fi ona iye pipe han won.
3f K'a ma te siwaju n'ise rere
K'a ma tele Kristi lojojo
Ka ma se 'anu gb'eni subu ro
K'a ma fi Jesu han asako.
Amin

21 8.7.8.7. & Ref.


Ko si igbala lodo elomiran nitori ko
Si oruko miran labe orun ti a fi fun ni
ninu eniyan nipa eyiti a le fi gba wa La.
Ie A 4:12

1 f Sa di oruko Jesu mu
N‘igba ibanuje re
Y'O si fi itunu fun o
Ro mo ni ibi gbogbo
Oruko...... Iyebiye
Ireti wa l‘aye yi
Oruko ....... iyebiye
Ayo fun awon t‘orun.

2 f Ma fi oruko Jesu se
Asa nigba idanwo
B'idamu kan ba de ba o
F'oruko na gbadura.

3f Ma iyebiye l'ooko Jesu


O nimu ki okan wa yo,
Gbat' apa 'fe Re ba gba wa.
A o korin iyin Re.

4 mf Ao juba oruko Jesu


Ao wole li ese Re
Ao de Oba wa l'ade
Gbat' tajo wa ba pari.
Amin.

22 12.9.12.9. & Ref.


Nigbana li a o si gba awa ti o wa laye
ti o si ku lehin soke pelu won sinu
awonsanma
Thess. 4:17

1 f Eje k‘a korin ti y'o da wa laraya


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Ile y‘o su a o si ji si ayeraye
Ko ni pe mo ti a o fi de 'le.
mp Laipe ao de ‘le, laipe ao de 'le
T'awa ti Balogun wa
Ao segun iku, ao pade lai pinya mo
Ko ni pe mo ti ao fi de ‘le

2 f Jek‘a gbiyanju k‘a sise tokan –tokan


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Ore ofe Re o s'agbara wa d'otun
Ko ni po mo ti ao fi d'le

3 E je k'a ran awon alailera lowo


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
K‘a fi ife f‘awon asako s‘odo Re
Ko ni pe mo ti ao fi de 'le

4 f Isimi daju a o bo lowo aniyan


Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Ko si ekun l'ebute daradara na
Ko ni pe mo ti ao fi de 'le
Amin.

23 12.12. & Ref.


Olorun mi gbom 'odo Re li o gbekele o la
OD.86. 2

1 f Igbala kikun ni Olorun se 'leri


F'eniti o ba gba Jesu omo Re gbo
Aleluya: O pari mo gba Omo gbo
Mo ri 'gbala ninu eje Olugbala.
Aleluya; o pari mo gba Omo gbo.
Mo ri 'gbala ninu eje Olugbala

2 f Bj ona mi tile kun fun ewu pupo


Dajudaju Jesu yoo mu mi laja.

3 f Olufe pupo ni mo ni l‘ode prun


Nwon wa ninu ogo, eyi si l‘orin won

4 Awon omode duro l'egbe Oba won


O nrerin si won bi won ti nkorin won.

5 f Woli at' Oba wa ni ipejopo na


Nwon nkorin bi won ti nla t‘ wura koja.

6 f Awa pelu ni lati ko n'nu orin na


Oro orin iyin wa titi lae leyi.
Amin.

24 11.6.11.6. & Ref.


E lo si gbogbo aye, ki e si ma wasu
ihinrere fun gbogbo eda
Mk. 16:15.
1 f Ipe na ndun l‘otun ati l'osi pe
Tan 'mole, tan ‘mole
Opo l‘o nku laini ireti orun
Tan ‘mole tan 'mole
f Tan 'mole ihinrere na
Je k‗ o tan yi aye ka
Tan 'mole ihinrere na
Je k' o tan yi aye ka.

2 f Awon t‘o wal' okunkun nke tantan pe


Tan ‘mole, tan ‘mole
Mu won wa jeje s' ibi agbelebu
Tan 'mole, tan 'mole

3 Je k'a gbadura k' or‘ ofe le joba


Tan 'mole, tan 'mole
Ki Emi Krist‘ joba ni ibi gbogbo
Tan 'mole, tan ‘mole

4 Jek‘ ateramo ise t'o l‘ere yi


Tan 'mole, tan mole
A o gbade nikehin bi a foriti
Tan'mole, tan mole.
Amin.

25 8.7.8.7. & Ref.


E ma sowo titi emi ofide
Luk 19:13

1 mp Un o ha lo ni owo ofo?
Ki nlo pade Jesu be?
Nko iti eise ojo kan fun
Nko iti mu enikan wa.
p Un o ha lo ni owo ofo?
Un o ha pade Jesu be?
Ko si eso kan lowo mi
Ti mo le mu pade Re?

2 mp Iku ko lo nderuba mi
Tori Jesu ti gba mi
Pe mo nlo ni owo ofo
Iro yi mb'okan mi je.

3 mp A! akoko ti mo sonu
Mba le pe won pada bo
Mba fi won fun Oluwa mi
Ife Re ni mo fe se

4 mp Enyin mimo, tara sise


Sise,'gbati se osan
Ki igbe aye yin to pin
So eso fun Oluwa.
Amin

26 8.8.8.8. & Ref.


Fa mi lo si Apata ti o ga ju mi lo
OD. 61:2

1 f Mo ntesiwaju l'ona na
Mo ngoke si lojojumo
mp Mo gbadura bi mo ti nlo
Oluwa jo gbe mi soke,
f OluWa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga
Apata t‘o ga ju mi lo
Oluwa jo gbe mi soke.

2 f Ife okan mi ko kuro


Larin 'yemeji at'eru
Awon miran le ma gbe be
Ibi giga l'okan mi nfe

3 f Mo fe ki nga ju aye lo
B'esu tile ngbogun ti mi
Mo nfi gbagbo gbo orin na
Ti awon mimo nko loke.

4 f Mo fe de 'bi giga julo


Ninu ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de be
Oluwa mu mi de 'le na.

5 f Fa mi lo si ibi giga
Laisi Re nko ni le de ‘be
Fa mi titi d' oke orun
Ki nkorin lati ‘ibi giga.
Amin.

27 11.11.12.9, & Ref.


Ile ti nsan fun wara ati fun oyin
Num. 14:8

1 mp Ite kan wa t'Olorun fife Re han


Ile rere to nsan fun wara at‘ oyin;
O si p‘awon T‘ire pe ki \
Nwon mo ‘le na
Ki nwon si gbe nile Oluwa
p Eyin t‘ a' rapada,
(Eni rapada gbo ase Kristi).
―Ma beru!‖ yan lo wonu
‘Le na fun ini
Wonu re, gbat‘ gbi jor-dan' duro
(Wo o n‘igbagbo, gbat' igbi Jordan‘duro)
mp Woni ‘e t‘Oluwa fifun o.

2 f Ajara, re so eso didun pupo


Awon igi ope re so jigbinni,
Awon isun omi re mu 'le na lora
Nibi nwon nrin nile Oluwa.

3 f Nile na or'-ofe segun gbogb‘ ota


Alafia Kristi segun gbogbo ibi:
Ife Olorun mu okan gbogbo gbona,
Nile t'a gbekele Oluwa.

4 f Nile na nibiti ‘mole ko dekun,


At‘orin ayo t'angel‘ fe lati gbo;
Nwon nwo Kristi, nwon ko si beru ibi
kan
Ko si 'beru nile Oluwa.

5 f Nihin, loke lo lao jogun ile na,


Krist‘ wa s‘ aye k‘a le d' eni ibukun;
Oro Re daju, pe a o wonu isimi;
'Gbat‘ agbekel‘ oro Oluwa.
Amin.

28 11.11.12.11.12.11 & Ref.


Alabukun fun li awon olokan-tutu nitori
nwon o jogun aye - Mat. 5:5

1 f Igba aye wa a ro gbede gbede


Igba aye wa a ro gbedegbe
Ka sa li beru Oluwa Oba Ogo;
Inu buruku, aso ka mukuro;
Ka toro fun suru, baba iwa ni;
Igba aye wa a ro gbedegbe‘

2 f Igba aye wa a ro gbedegbede;


Igba aye wa a ro gbedegbe
K‘a ma se f‘iwa ipa so ara wa degbin;
Ejo pelejo, odi, ka mu kuro;
K‘a yera fun ridimo ipa osi ni;
Igba aye wa a ro gbedegbede.

3 f Igba aye wa ro gbedegbede;


Igba aye wa a ro gbedegbede
Ka sa ma yo n'nu Oluwa
K‘a wa Ogbon;
Ife inu ‘re, ayo ka fi josin
K‘ododo kun emi wa, ipa iye ni;
Igba aye wa a ro gbedegbede.

4 f Igba aiye wa a ro gbedegbede;


Igba aye wa a ro gbedegbede
K'ani ife bi Olorun ti se fe wa;
Ati bi t' alanu ara Samaria;
Pelu 'reti to daju ni aye ti mbo;
Igbe aye wa ro gbedegbede
Amin.

29 HC.519 7s 6s & Ref.


Bi enikeni ba sin mi ki o ma to mi lehin
John 12:26

1 mf Mo ti se‗leri Jesu
Lati sin O dopin
Ma wa lodo mi titi
Babami, Ore mi
Emi k‘yo beru ogun
B‘Iwo ba sunmo mi
Emi ki yo si sina
B‘o ba fona han mi.

2 Je ki nmo p‘O sunmo mi


‘Tor‘ ibaje aiye
Aiye fe gba okan mi
Aiye fe tan mi je
di Ota yi mi kakiri,
Lode ati ninu
cr Sugbon Jesu, sunmo mi,
Dabobo okan mi.

3 p Je ki Emi k‘o ma gbo


Ohun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiyeyi
Titi, nigbagbogbo,
cr So, mu k‘ o da mi loju
K‘okan mi ni ‘Janu
So si mu mi gbo Tire
‘WO olutoju mi.

4 mf ‗Wo ti seleri, Jesu


Fawon t‘o tele O
Pe ibikibi t‘ O wa
L'awon y'o si wa
Mo ti se 'leri Jesu,
Lati sin on O dopin
Jeki nma to O lehin
Baba mi, Ore mi.

5 p Jeki nma ri 'pase Re


Ki nle ma tele O
Agbara Re nikan ni
Ti mba le tele O
To mi, pe mi, si fa mi
Di mi mu de opin
Si gba mi si odo Re
Baba mi, Ore mi.
Amin.

30 8.7.8.7. & Ref.


Oungbe Olorun ngbe okan mi
OD. 42:2

1 f Mo ni lati ni O, Jesu
Nkoje da ona yi rin
Mo nfe ri O nitosi mi;
Fi Owo Re yi mi ka
mf Emi k' yo berukeru
To mi sibi t‘O ba fe
Tayotayo l'emi yo lo
U n o ma to‘pa-se Re lo

2 f Mo ni lati ni O, Jesu
Igbagbo mi ko to nkan
Oro itunu Re nikan
Lo le fun mi l‘agbara.

3 f Mo ni lati ni O, Jesu
L‘Ona ajo mi s'orun
Ninu ojo tabi iji
Ninu ogun gbigbona.

4 f Mo ni lati ni O, Jesu
Ki oju Re ma to mi
Titi un o de odo Jordan‘
Ti un gunle sodo Re
Amin.

31
H.C. 548 .C.M
Gba mi la nitori anu Re – ps. 6:4

1 mp Baba ma yi oju kuro,


Fun emi otosi;
Ti npohunrere ese mi
N‘iwaju ite Re
2 ‗Lekun anu t‘o si sile,
F‘akerora ese
P Mase ti mo mi Oluwa
Je ki emi wole

3 mp Emi koni pe mo njewo


B‘aiye mi ti ri ri;
Gbogbo re l‘ si‘ehin wa, ni
‗Wo mo dajudaju
4 mf Mo wa si‘lekun anu Re,
Nibiti anu po
Mo fe ‗dariji ese mi,
K‘o mu okan mi da

5 mf Emi ko ni ma tenumo
Itunu ti mo nfe;
‗Wo mo, Baba, kin‘ to bere,
Ibukun t‘emi nwa

6 cr Anu, Oluwa, ni mo nfe


Eyi-yi l‘opin na;
Oluwa, anu l‘o ye mi,
Je ki anu Re wa.
Amin.

32 H.C. 231: tabi t H.C 205 D.C.M


Oluwa awon omo-ogun, on na li
Oba ogo – Ps. 24:10
1 f Gbe ori nyin s‘oke, eyin
‗Lekun aiyeraiye;
Gba oba ogo; wo, o mbo
mp Ta l‘Oba Ogo yi? Tani?
cr Oluwa t‘o ni ipa
f To lagbara l‘o or‘ota Re.
Asegun, Alade

2 mf Gbe ori yin s‘oke enyin


Ilekun; lati gbaa
f Oba ogo; pe wo, o mbo
Pel‘ogun didan Re
mp Tal‘oba Ogo yi?
cr Oluwa t‘o n‘ipa
Ta f‘ogo de l‘ade
Amin.

33 H.C. 480 C.M


Kiyesi! Oba re mbo wa sodo re o ni
Irele o si gun ketekete. Sek 9:9
1 f ‗Gba Jesu f‘ite Re sile,
p O mu ‗po irele,
Ni ‗rele o mu awo wa,
pp O wa gbe ‗nu aiye

2 p A ba le rin bi on ti rin,
Nipa ona ogbon;
K‘a dagba l‘ore at‘ogbon,
Bi odun ti npo si

3 mf Oro didun ati erin


Gba ‗won iya to wa,
L‘o figbe omo won mora,
T‘o sure fun won

4 mf A ba le wa l‘alafia,
L‘apa Olugbala,
K‘a bo low ‗baji aiye,
Labe itoju Re

5 f ‗Gba Jesu gun ketekete


Awon ‗mode nkorin;
f L‘ayo, nwon ka eka igi,
Nwon te ‗so won sile

6 f Hosana l‘a ba ko lorin


Hosanna s‘Oba wa;
ff B‘a ba gbagbe iyin Jesu
cr Okuta y‘o korin
Amin.

34 Tune: S.S 153


―Sibe ninu aisan re Asako wa Oluwa bikose ‗awon onisegun, O si ku‖
II Kro 16:12-13

1 Ma gbekel‘onisegun n‘tori‘
ese ni
Isegun kan yi o tun fun o
Lagbara
Woke pelu ‗gbagbo ‗wo yo
Si bori
Sa sunmo Jesu si On yio mu
O laja
Bere pe k‘Olugbala
K‘O di o mu k‘o gba o
O nfe mu o larada
Yio mu o laja

2 K‘ona ogun sile patapata


Gbekele agbara Olorun
nikan
J‘oloto, si duro pelókan
Funfun
Sa ma sunmo Jesu si, On
Yo mu o laja

3 Olorun yo f‘okun f‘enit‘o


Gbagbo
A o segun ao bori nipa
Igbagbo
Olorun yo so agbara wa
Dotun
Sa ma sunmo Jesu si,
O n yo mu o laja
Amin

35 O.t.H.C.247 D.S.M
H.C. 257
Nwon si kun Emi Mimo – Ise 2:4
1 mf Emi Olorun mi
L‘ojo ‗tewogba yi,
Gege bi ojo Pentikosti
f Sokale l‘agbara
lokan kan l‘apada
Ninu ile re yi:
A duro de ileri Re
A duro de Emi

2 p B‘iro iji lile,


Wa kun ‗nu ile yi;
cr Mi Emi isokan si wa,
Okan kan, Imo kan,
Fun ewe at‘agba
L‘ogbo at‘oke wa
Fi okan gbigbona fun wa;
K‘a yin, k‘a gbadura

3 mp Emi Imole, wa
Le Okunkun jade;
Siwaju ni ki ‗mole tan
Titi d‘osan gangan
Emi otito wa,
S‘amona wa titi;
Emi isodomo, si wa
S‘okan wa di Mimo
Amin.

36 H.C. 441.10s
1 mp Mura tan k‘o gba Ara
Oluwa
Kó mu Eje mimo t‘a ta
Fun o

2 Ara at‘eje na ló gba o la


cr N‘itura okan, f‘ope f‘Olorun

3 f Elebun igbala, Omo Baba


Agbelebu Re fun wa
n‘isegun

4 di A fi On rubo fun t‘agba t‘ewe


On tikarare l‘Ebo, On l‘Alufa

5 mf Gbogbo ebo awon ju laiye


‗gbani
J‘apere ti sno t‘Ebo, ‗yanu yi

6 On l‘Oludande, On ni imole,
On nf‘Emi ran awon Tire lowo

7 mp Nje e fi okan gbagbo mura


Ki e si gba eri igbala yi

8 mf On l‘o nsakoko enia Re laiye


On l‘o nf‘iye ainipekun fun wa

9 f On f‘onje orun f‘awon t‘ebi n


pa
Omi iye fun okan ti npongbe

10 p Onidajo wa, Olugbala wa


Pelu wa ni ase ife Re yi

37
Kristi eniti ise iye wa – Kols 3:4
1 Mo nsin Jesu t‘o jinde,
Okanna ni loni
Mo mo pe O mbe laye, bi
Nwon tile nkegan
Mo ri owo anu Re, mo
Ngbohun Re didun
Nigba mo fe ‗ranwo Re,
O mbe n‘itosi
O mbe laye, O mbe laye
Sibe
O mba mi rin lojojumo li
Ona toro yi
O mbe laye, lati mu ‗gbala
Wa
B‘o ba fe mo p‘O mbe laye?
O ngbe ‗nu okan mi
2 Li ayika mi gbogbo mo
Mo nri itoju Re
Lati tile mu mi emi ko je
Damu
Mo mo yio mu mi la gbogbo
Idanwo ja
Ojo ifarahan Re y‘o de laipe

3 Onigbagbo, bu sayo, gbe


Orin yin soke
Korin Halleluya si Jesu
Kristi Oba
Ireti ati ‗ranwo awon ti
Npongbe Re
Ko s‘oninure bi Re laiye,
L‘orun

38
1 Ile kan mbe t‘o dara julo
A le f‘igbagbo ni ile na
Nibiti Baba nduro de wa
Lati fun wa n‘ibugbe nibe
Pel‘ayo.....nigbose
L‘ao pade l‘ebute didan wa
Pel‘ayo....nigbose
L‘ao pade l‘ebute didan wa

2 A o korin l‘ebute didan wa


Orin t‘awon alabukunfu
Ko ni s‘ibanuje fun wa mo
Kiki ‗simi didun at‘ayo

3 Ao korin iyin si Baba wa


Fun ore ofe Re lori wa
Fun ebun ofe ti Omo Re
At‘ibukun t‘a ko le ka tan.
Amin

39
Gba Jesu Kristi Oluwa gbo a o si
Gba o la – Ise Apos. 16:13
1 Gbo iro ayo didun
Pe Jesu ngba ni la
Kede re jakejado
Pe Jesu ngba ni la
Tan ihin ayo na ka
Lor‘oke on petele
Kede re kikan-kikan
Pe Jesu ngba ni la
2 So fun awon to jinna
Pe Jesu ngba ni la
F‘awon to wa nitosi
Pe Jesu n gba ni la
So fun gbogbo elese
Ore at‘ibatan re
So tii idasile yi
Pe Jesu ngba ni la

3 Korin irapada na
Pe Jesu ngba ni la
O ti ku O si jinde
Pe Jesu ngba ni la
Korin na lohun jeje
Fun oakn to nwa anu
Ko orin isegun wa
Pe Jesu ngba ni la

4 Ki gbogbo wa korin na
Pe Jesu ngba ni la
Ki gbogb‘aiye bu s‘ayo
Pe Jesu ngba ni la
Ofe ni gbala na
Igbala kikun si ni
Orin isegun l‘eyi
Pe Jesu ngba ni la

40
E ma wa inu Iwe Mimo – John 5:39
1 So itan ti Jesu fun mi
Ti mo feran;
Gbogb‘ohun ti ba so fun mi
B‘O mbe nihin
Ti eba ona
Ati t‘okun,
Itan ti Jesu
So won fun mi

2 Ko so bi awon omode
Ti yi I ka;
Ki emi le ro pe ‗bukun Re
Ba lori me:
Oro inure
Ise ore
N‘nu mole ife
Oju Jesu

3 Mba le ba egbe omode


Wo nu ilu
Pelu eka igi ope
Li owo mi;
Bi akede Re
Ni mba korin
Wipe, Hosanna!
Jesu joba!

4 So fun mi bi igbi okun


Ti nyi ridi
Bi iji ti ndamu oko
Ni Galili
Ati bi Jesu
L‘ohun jeje
Ti ba igbi wi,
T‘iji si pa
Amin.

41
Emi li Oluwa ti a mu o lara da
Exo 15:26
1 Mo gbekel/onisegun, n‘tori
Ese ni,
Isegun kan y‘o tun fun o
L‘agbara
Woke pelu gbagbo ‗wo y‘o
Si bori
Sa sunmo Jesu si
O n y‘o mu o laja
Bere pe k‘Olugbala
K‘o di o mu k‘o gba o
O nfe mu o lara da
Y‘o mu o laja

2 Ko ona ogun sile patapata


Gbekele agbara Olorun
Nikan
J‘oloto, si doru pel‘okan
Funfun sa sunmo Jesu si
O n y‘o mu o laja

3 Ohun y‘o f‘okan f‘eniti


O gbagbo
A o segun ao bori nipa
Igbagbo
Olorun y‘o so agbara wa
D‘otun sa sunmo Jesu si
On y‘o mu o laja

42
Ore kan nbe ti o fi ara konrin lo
Owe 18:24

1 Kos‘ ore be Jesu onirele


Kos‘ore bi ti Re
Kos‘onisegun to le w‘ese san
Kos‘ore bi ti Re
Jesu mo gbogbo ‗jakadi wa
Y‘o ran wa lowo de opin
Kos‘ore bi Jesu onirele
Kos‘ore bi ti Re

2 Kos‘ ore to ga bi Re ni mimo


Kos‘ore bi ti Re
Kos‘ore to n‘irele bi ti Re
Kos‘ore bi ti Re

3 Kos‘ akoko kan ti ko sunmo


Wa
Ko s‘ore bi ti Re
Ninu ‗danwo y‘o ma tu wa
Ninu
Kos‘ore bi ti Re

4 Ebun kan ha wa to ju Jesu


lo?
Kos‘ore bi ti Re
Y‘o ha ko fun wa k‘a n‘ile
L‘orun?
Ko je ko! Ko je ko!
Amin

43
O si mu awo iranse....O si teriba titi
De oju iku.........Fil. 2:7-9
1 Okan at‘ohun mi
Ni ngo fi yin Jesu
Ki gbogb‘aiye yin Oluwa
O njoba ni gbogb
Aiye ati orun
Eniti o da ohun gbogbo

2 O wa bi iranse
Ninu awo eda
O gba egun wa s‘ore Re
O fi ‗ra Re rubo
O ta je Re sile
Lati so wa d‘ominira

3 Asegun ti jinde
O bori ota Re
O si di wn ni igbekun
O fo ijoba won
O mu won jewo pe
Kristi l‘Oba gbogbo aiye

4 Ninu anu Re nla


L‘o fi njboa l‘aiye
Ninu ogbon at‘ododo
Eni to Jesu wa
Y‘o to ife Re wo
Y‘o ri ‗gbala nal gba lofe

5 Oba alafia
Ki ijoba Re de
Ki gbogb‘ aiye ri ogo Re
Titi ododo Re
Ati iwa mimo
Y‘o gbile ninu aiye yi

44
Eniti eniyan fe lairi. 1 Pet. 1:8
1 Olugbala wa owon
B‘a ko tile ri O
Awa fe Oruko Re
Ju gbogbo aiye lo
Awa wole a njuba
Si O l‘awa nkorin
Iwo l‘awa nfi ‗yin fun
Oluwa, Oba wa

2 Iwo t‘o mu ‗gbala wa


T‘o nsise ninu wa
T‘o nfi ara Re han wa
Ju gbogbo ero wa
Awa wole a njuba
Si O l‘awa nkorin
Iwo l‘awa nfi ‗yin fun
Oluwa, Oba wa

3 Gbogbo ekun ibukun


Gbogbo ore ofe
Gbogbo agbara mi
Ninu Re l‘a le ri
Awa wole a njuba
Si O l‘awa nkorin
Iwo l‘awa nfi ‗yin fun
Oluwa, Oba wa.

4 Se wa ye fun ‗joba Re
K‘a le korin l‘orun
Ninu imole titi
At‘ayo ailopin
‗Gbana l‘awa o yin O
Si O l‘awa nkorin
Ninu l‘a ma jewo Re
L‘Oluwa, Oba wa

45
Mo ri Oro re mo si je won
Matt. 9:2

1 Ma je k‘oro na koja lo,


K‘o si d‘oju si ‗mole yi
Elese s‘okan re paya,
Gba ‗gbala l‘ale yi
Ki lo se ti ko j‘ale yi;
Ki lo se ti ko j‘ale yi
(Ti ko j‘ale yi, je ale yi)
O ha nfe igbala, je ko j‘ale yi
(O nfe igbala, O nfe igbala,
Je ko j‘ale yi)

2 Orun ola le saimo


Lati bukun okan ese re
Akoko na de, ologbon
Gba ‗gbala l‘ale yi

3 Aanu Olorun wa sibe


‗Wo k‘yo wa si ‗nu ‗fe Re
Ko iwa ese re sile
Gba ‗gbala l‘ale yi

4 Aiye ko n‘adun kan fun


Ko si ohun rere kan nibe
Joo to aiye Kristian wo,
Gba ‗gbala l‘ale yi

5 Oluwa k‘yio ko o sile


Bi o ba f‘okan re fun
Igbaagbo ise naa ti pari
Gba ‗gbala l‘ale yi
Amin

46
E wa sodo mi gbogb eyin ti a di eru wiwo le lori, Emi o fi sinmi fun yin.
Matt.11:26

1 Wa iwo t‘eru ese npa,


Alanu ni Jesu
Idariji mbe ni Kalfari,
Jesu sunmo tosi
Idariji mbe ni Kalfari,
Kalfari, Kalfari,
Idariji mbe ni Kalfari
Jesu sunmo tosi

2 Gb‘aini re to Jesu loni


Le eru re sonu
Idariji mbe ni Kalfari
Jesu sunmo tosi
Idariji mbe ni Kalfari,
Kalfari, Kalfari,
Idariji mbe ni Kalfari,
Jesu sunmo toisi

3 Okan re ha nep o
Olugbala npe o
Idariji mbe ni Kalfari
Jesu sunmo tosi
Idariji mbe ni Kalfari
Kalfari, Kalfari,
Idariji mbe ni Kalfari
Jesu sunmo tosi
Amin

47
Won si kun fun Emi Mimo
Ise A. 2:4
1 Emi Mimo wa l‘ojo Pentecost
O wa ninu agbara nla
Eri Re pel‘onigbagbo ngbala,
Opolopo lo di atunbi
Awin Krisitan akoko ka kiri
Nwon nso ‗hinrer laiberu
Opolopo lo di ajeri ‗ku
Nwn nkoja lo ni isegun
Wa Emi Mimo, Okuku su,
A nfe ekun Re, Ife, agbara
Nla Re
Rin wa aarin wa, ru wa s‘oke
Wa Emi Mimo, so iji ji loni

2 Ati nigbati ‗kuku bo aiye


Olododo ye n‘nu ‗gbagbo
Emi Mimo so ijo d‘atunbi
T‘ina isodotun njo
Ati nigbati isoji ba de
Ati nigbati isoji ba de
T‘olododo si ngbadura
Anfe ina mimo yi lekan si,
Lati b‘akoko yi pade
Amin

48
Oluwa Iwo n mo gbe okan soke si
O.D. 25:1

1 Kristi Olugbala wa n‘nu ogo


Lati gb‘elese ninu egbe
L‘ori Re ni a fi ade egun;
Ni Kalfari loti ru ebi mi
On gbe loke, On gbe loke
Bori ese ati omo ogun re
On gbe l‘oke, On gbe l‘oke
L‘ojo kan on pada bo wa

2 O jinde ninu iku ‗banuje


Lati gbe n‘nu ayo ati ife
On pada bo li ojo ayo kan
Lati k‘awon omo Re re ‗le
l‘oke

3. Okan are sa to Jesu loni


Gba irapada to fi fun o,
Saa wo Jesu ki o gba ibukun
Iye mbe ayo mbe ati ‗segun

49
Wo o, Oko Iyawo mbo. Matt. 25:6
1 Oju mi ti ro ogo ipadabo
Oluwa
Yi o segun iku ati gbogbo
Ipa agbara re
O tu awon olooto ninu imole
Ogo Re
Ooto On siwaju
Ogo,ogo halleluya;
Ogo, ogo halleluya,
Ogo, ogo halleluya,
Ijo ntesiwaju

2 Mo ri ninu ogo egbegberun


Imole orun
Lori ite ewa iwa mimo ti
Igba asale
Mo le ka ododo ati ewa
Mimo Re
Awa nte siwaju

3 Oun agogo orun ndun wipe


Ka tesiwaju
On so fun gbogbo eniyan pe
Idajo Re fe de,
Mura tan iwo okan mi k‘o si
Bu s‘orin ayo
Awa nte siwaju

50
Ife gbogbo Orilede yoo si de
Hag. 2:7
1 Gbo orin awon Angeli
Yika ite Re
Gbogbo wn nlu duru wura
L‘osan at‘oru
Egbegberun awon mimo
Njewo pe Jesu l‘Oba

2 Iwo ti ngbe n‘nu mole nla


T‘eda ko le wo
Sibe iwo nfe lati gbo
Orin iyin wa
A be le mo p‘O sunmo wa
Lati gbo adura wa

3 A F‘ara Wa Rubo Fun O


Ninu ile Re
Gba okan wa, owo ese,
Ati ohun wa
Ya won si mimo fun lilo
L‘aiye yi ati l‘orun

4 Ogo, ola ati iyin


L‘ao ma fifun O
Baba, Omo ati Emi
Meta n‘nu okan
Opo ‗bukun t‘o nfifun wa
L‘awa tun nfun O pada
Amin.

You might also like