Professional Documents
Culture Documents
Toaz - Info Iwe Irawo Prof Converted 1pdf PR
Toaz - Info Iwe Irawo Prof Converted 1pdf PR
Gbogbo iwe ti ase jade loni aworan Prof Awo Irawo ninu titori idi eyi sora lati ra aiye deru iwe
Tel : 00229 62344788 0023408098692587
roufai.mohamed@facebook.com
Ki oluwa maje ki ase ise onise ; Eni se ise onise loman pariwo kiri ile
adahunse pe aiye nse ohun ; Eni mu ise re pon tosi yori si rere lomo araiye ma as
ope omu lukudi, ose ogun awure sibi oja re ati bebelo, ile aye konira rara, eda inure
ti nwon nse ise onise ni zon npariwo enu pe ita le, kosi owo lode ati bebelo : eni
irawo re se ise jagunjagun bi aries ti nlo ta eja enia o timo pe osina
Eyin oluka iwe yie e fi ara bale ka iwe yi tan sn ki oronu re wo daradara ki
oranti olorin tio o ko bayi pe \ ki aiye mama pa kadara wa da, ara nbe ta fe da eyi
tu ;osi pe onan ise asela ohun lohun wa yi sugbon awon ti won se ise onise ti won
jowu ohun, ki won ma le ranti ati gbe ti ohun se,
Gbogbo wa lamo pe awon ti won se ise onise lati aro di ale, pupo ninu won
ti won o ba ni emi olohun ninu ti won baranti awon ti won jo betre ti won ti ni lari,
biri tiwon ba yi pada won aparada di Asa ti o ngbe o omo adie je ;
Iwo ti osi wa ni idi ise boya eni oda, ola ada, ron piwada, masin ori olori ku,
mu ona ise asela re pon oluwa yio mu e yori e si rere ki otodi ojo ale ; Iwo ti oba si
ti gbo ma pada di asa, toju iwe yi fun omo ti oba bi yio wulo fun, Ranti npe iran
meta kole to si po dandan ari eyi ti o jana ; Ranti Iran tie ti omadi oloro lehin ola
dandan Asa Egbe re toba ku lehin loma gbe iran re ti oloro mi ; Iwo ti osi mo ijo ti
abie ti o kosi fe se ise onise, jowo pe mi sori number mi
Opo Obi loti da igbese aiye omo re ru nipa pe dandan ise bayi bayi ni o
gbodo ko, Olukuluku eda ni Olohun ti fun ni ise ti yio maa se laye, sugbon latari
agidi ti awa omo Eda Adamo ni koje ki a ni ifura. Oro Olohun ko le ye omungo
Eda sugbon Ologbon eni ni nye, Opo ti o yeki o lo se ise Briclayer sugbon alani
akiyesi ko je ki o tete yan ise ori re layo, Eda ti o baa je omi laye ti o baa nse ise ina
kole ni aluyo laye, eda to si je ina ti o nlo nse ise omi kole ni ilosiwaju laye. Imo
nipa Irawo se koko laye awa omo eda, eleyi a jeki eda mo iru igbese aiye ti o le gbe,
ohun ti oye ki a maa se ati ohun ti koye ki ase. Eda ti OIohun da lati ara omi ti o
waa nlo se ise ni ile ise Bread, ki se epe raara kole ni aluyo laye. Ti abati bi omo
Ejeki a gbiyanju ki a to awon to ni imo nipa Izab wiwo ki won se alaye lori Iru
irawo ti omo naa gbe waa si aiye, iru ise ti ole se. Esu koni da irin Ajo gbogbo waa
ru mo wa lowo laye. Amin
Igbeyawo kiise ohun ti ole wole ki osare jade, idi niyi ti yoruba fima nso
ni oro wipe oloko meji koni duro lori eyokan oro yi wa fun awon ti oba sina fe
oko oloko papa awon ojise olorun alfa ati adahunse ma ntan opolopo eniyan je
won aba won ye ise wo won a ni awon ri ibujoko wa nibe nitori awon ri omo
larin won oto ni ki irawo oko ati iyawo ba papo oto ni pelu ti irawo oko ati
iyawo ba funwon ose wo. Iwo ti oba si ti lofe okoloko ti omo bati wa larin
igbeyawo yin mase fi oko e sile sugbon toju Iwe yi fun awon omo re nitorie ojo
iwaju ki omobatun ri biti tire. Mo loba enikeni mo rara, wo ojo ibi ti iyawo ati ti
oko ki ofimo boya oto kiwon fe ara tabi ko to. Ni naye ojosi, ama nwadi idile ti
omo wa ti fe loko tabi ni aya sugbon ni ode oni kosi iru e mo, ife ni won nlo fi ni
oko tabi aya. Omo ti oba fi ara bale yio gbadun igbeyawo re de ojo ale.
Eyiti koba fi ara bale ni oro olopko meji koni duro lori eyokan. Ti iru
awon wonyi ko ba rora se won yoo di oloko meta koni duro lori meji ati papa
oloko merin koni duro lori meta, awon miran atun ni irun eni bayi kolori oko
laimo wipe gbogbo eda ti oba konju ni oko laise iwadi lori irawo won boya oba
ra mu tabi koba ara won mu yoo kanju jade.
Mase gbagbe wipe oja meji ni awa na ni aye, oja akini mofe ra motor,
aso, bata ati bebe lo, wa mu ojo losi oja lati eyeti odara ; sugbon oja keji mofe fe
oko mofe fe iyawo odi dandan ki o mu ori lo, or iwa koni tiwa lofe oko oloko
tabi aya alaya amin fun alaye ni eku rere tabi oni ikose lori igbeyawo re tabi
igbeyawo re koso eso rara etc….. yowo gbiyan ju lati ri Prof Awo Irawo
Aries belier ; Taurus tauraux ; Cancer cancer; Germini germaux ; Leo lion;
Lotito ni opo ninu awon Onimimo nipa Irawo ko fi owo si ajogbe Irawo
Omi ati Ina, nitori Omi yoo pada Pa Ina, Sugbon won le jo da Ise po won sile
fera won ti won ko ba jo gbe papo lo dara ju nitori Ija. Koda won le ma ba ara
won Sore, sugbon won yoo pada tuka pelu Ija tabi lori Ireje ti yio ma sele larin
ara won pelu aifinu han ara eni tan.
Awon Onimimo nipa Ijinle Irawo tako Ajogbe Irawo Omi ati Afefe, nitori
wahala ati idamu ti afefe saaba ma nkoba Omi, sugbon won le fera won gegebi
toko taya won si le jo sore tabi ki won jo da Ise po bio ti je pe won yo tete ma ri
asise ara won ki si nii si Igbadun fun Afefe pupo nitori Afefe yoo ma fe si Omi
Omi yo si ma tan kakiri eyi tumo si wipe Omi ni ajogbe won yo gbe pupo.
Ajogbe awon Irawo yerupe ati yerupe dara pupo oore si ma nbe nibe
ajogbe won Ti o ba je wipe yerupe ati yerupe ba fe ara won tabi won mu ra won
ni Ore tabi won jo da Ise po odara pupo won ki si ri Inira tabi Ija rara Afi ti
eniyan kan ba wo won larin ni o le fa Ituka. Be sini Adamo yerupe ati Omi naa.
Awon Ojogbon ninu Imo Adamo ko fi ara mo Ajogbe Irawo yerupe ati
afefe nitori wahala ati fitina ti Adamo Afefe ma nko ba Irawo yerupe sugbon
won le fera won gegebi toko taya ti won ba fe ki Ajogbe Ife naa pe dada won le
ma gbe papo ninu ile kunna nitori ti o ba je Okunrin ni Irawo Afefe koni ma fi
Ife han si Adamo yerupe gbogbo owun ti Irawo yerupe ba se ni ko ni mo se loju
Irawo Afefe yo tete ma ka ese si lese, won le mura won ni Ore won si le da owo
papo sugbon Afefe yo ma re yerupe je
Ajogbe Irawo Ina ati Ina ni o dara ju lati fe ara won tabi ki won mura won
ni Ore, won si le jo da owo papo Oore nla nla si ma njade ninu Idawole won
papo won fitina tabi wahala kii si sele larin ara won Ayafi ti awon iyawo won ba
tuwonka loku ti o baje toko taya ni awon molebi ni won ma nda arin won ru tabi
Ore Bakanna…
1. IRAWO AFEFE
Je eniti yio maa se Adua daadaa, ki osi maa tan Turari pupo ni igbati o baa
nse Adua lowo, Maa lo Turari Adua dada ni gbogbo igba, Aseje, Ose, ati Etu ntete
maa nsise lara iru irawo yii nidiwon ti won baa nti nse adua ki won to lo
2. IRAWO OMI
Ki won je iru Eda ti o nlo unkan ti won fi omi pipe, gegebi Hantu mumu,
Obe Aseje tabi ki won maa we ose dudu. Ebu Jijo ki sise lara won, bi won baa fi
one million se ebu fun iru won kole ri one naira ni ibe.
3. IRAWO INA
Irawo ina gbodo sora fun wiwe ose ni gbogbo igba, Ohun ti o dara fun iru
irawo yii naa ni Ki won maa lo Ebu ti a jo.. Ebu ni o nsaba maa sise pupo fun won
ju gbogbo ogun miran lo, Awon Ogun miran naa maa nsise fun won sugbon ko
dabi ki won lo Etu
4. IRAWO IYEPE
Irawo yii gbodo maa se Sara Daadaa, ki won maa fon awon unkan jije si ile
fun awon eda ti won nse aiye iyepe, Ose Dudu ati Aseje dara pupo fun won
AKIYESI PATAKI
Opo igba ni awa omo eda nsun gbagbe, opo ninu eda ni koni akiyesi, opo
lo ti lo se ayewo si oro aiye re ti obaa de ibi kan bi won ko ba so wipe awon agba lo
nda lamun won asope iya re ni o waa ni idi oro re, igbamiran won a ni egun idile,
ohun ti awa omo eda nfi owo ara waa faa gan ngba miran gan ju ki awon apapo
agba ma da enia lamun lo. Ojo kokan ninu osu loni ohun ti o nba enikokan wa rin,
Irawo ati Ojo ibi maa nda opo eda lamun, ,, opo igba loti lo ogun dudu sibe sibe
pabo lo nja si, boya eleda re ko lo ni ilana unkan be sibe sibe o ko agidi bori oni
dandan iwo naa fe se ogun osole!
1) Irawo Omi,
Ewe ki je lara iwo omi, ogun asasi ota ki si saba ran won, Je enikan ti yio maa saba
lo Hantu, tabi ki o maa se Adua si omi, Ebu lilo ki je lara won, bi won ba fi
Millions se Ebu fun won ko le sise, Ose si nma nsise die die lara ju Ebu lo
IKILO: E maa sora fun iwa akoba lenu ise, ki e ma ba eni keni ledi apo po se
ohun to lodi si ofin, ki e maa ba kabamo. E ma se kegbekegbe ni ibi ise, e sora ki
e ma gba ija onija ki eleyi ma baa yori si ota. E ma se wahala aseju lori ise ti ko
nilaari, e maa se suuru fun gbogbo nnkan ki e si sora lati ma wo aago alaago
sise. Won je eniyan ti o ma an tete nilaari ni igbesi aye won sugbon ki won ma
se je ki ola bo won loju lati ma le se ife Olorun. Paripari re ni pe ki won sora fun
iwa buburu lati hu si eni keni.
E je iru eniyan ti ko gbodo fi aye sile fun igaara tabi iwa emi ni mo to yii,
bi e ba se bee asilo agbara ti Olorun fun yin ni, o si le yori si isubu tabi iparun
ojiji. Nigba miiran emi itara ati aapon ti e ni yoo maa ti yin, o si le so yin di
alailero tabi alaini suuru. Nipa aironu jinle ki a to se nkankan tabi aifi suuru se e,
eyi le koba eniyan ki onitohun si fi owo ara re fa isoro tabi yanpon-yanrin ba
ara re.
E sora nipa fifi agidi tabi tipa-tikuuku je asiwaju, e ma se je ki inufufu bo
yin loju, ki e si ti ipa bee huwa tabi soro ti ko ni tan nile. E ma se je ki aifarabale
mu yin huwa tabi soro ko-a-tan, ni igba pupo, o le je iwa enu fifun tabi gbigbe
ara eni ga ju bi a ti to lo ni a o fi fa akoba fun ara eni.
Nipa aile ko ara eni ni ija nu tabi fi asiri ara eni pamo, ko dara ki e maa fi
gba bo oro ti e e ba gbo lenu eni keni se ibinu, ifarada se pataki julo.
E gbiyanju lati le maa pa asiri ara yin mo ati ti awon elomiiran, iwa aleebu
yin kan tun ni eyi. E ma se taku si ibi ise ti ko fun yin ni ere, ki e ma si se je ki
ija onija di tiyin, e ma si se gbagbe tati fun ara yin ni isinmi. E ma se fi oro
tembelu eni keni tabi yaju si eniyan e ma si se jo ara yin loju nipa agbara, e
gbiyanju lati maa gba imoran. Eyin obinrin, e maa bowo fun oko yin, ki awon
okunrin si maa toju iyawo won.
ILERA : Aisan ti yoo maa yoju si won ni efori, otutu, oju didun, iba, ooyi, ara
riro ati eje riru.
ISE : Ise ti o dara fun won niwonyii : Ise ero lorisirisi ona, oselu, ina monamona
(electrical work), hoteeli (hotel), owo sise ati akowe oja. Won si tun le se ojise
Olurun, olopaa, onisegun (doctor), akowe labe ijoba, gbogbo ise ni o ba won
lara mu sugbon iseda won ko ba eniyan da ise po, ki won sora fun inakuna.
April 22 – may 22
Oruko Irawo akoko yii ni ‘’Tauros’’ Omo ti a ba bi lati April 22 titi de
may 22 yoo je eniyan jeeje ti kii tete binu, sugbon eekan ti ibinu iru won baru
soke, won kii tete gbebe. Ahun ni won nitori pe won hawo. Bi o tile je pe alaanu
ni won, sibe won maa n wonkoko mo ohun ini won ju bi o ti ye lo. Iru won se ba
keebe, ologbon ni won, iruwon ni ipamora, won si maa n tete faramo samooni
iyowu ti o de si won. Won feran alaafia ati irepo lopolopo. Won kii si ko lati
maa fi egbin mora nigba miiran tabi lati padanu ohun kan ki irepo ba le wa ni ibi
kibi.
Iru won je eniyan ti o n duro tinpinnu tabi ileri won. Eyi si le je pelu ori
kunkun ati aife se ayipada okan nigba miiran.
Irawo ti n joba igbesi aye won yii naa ni n joba oro ife, eyi yoo fun won ni
abuda ati iriri ti o ni ise pupo pelu awon abinrin ati okunrin. Irawo wonyii je eyi
ti o fun won ni emi iforiti ati opolopo suuru. Won je eniyan ti won feran lati maa
fi eto ti o gbamuse se ohun gbogbo, won yoo feran ohun ti o lewa, oso sise ati
nnkan osin. Ti won ko ba sora, obinrin ti kii gbele oko ni won o fe sile, ni
warasesa ni won yoo salo. Won o ni owo sugbon inukuna ni won o maa na an.
ILERA : Aisan ara bi ofun didun, ara riro, eje riru, ori fifo ati inu rirun po fun
awon irawo yii. E sora gidigidi nipa ounje jije lode, ki o ma je pe ibe ni won yoo
ti fi majele sinu ounje fun yin ti yoo si se iku pa yin tabi ki e ri aisan nibe. Nipa
ti obinrin, aisan ara ti o je mo ti ibimo le maa yo won lenu, sugbon o seese ki
yipada maa wa fun won ni odun kefa-kefa ni gbesi aye won.
ISE : Ise ti o dara fun won ni oja tita sugbon to dara ki won ba eniyan da owo po
Orisirisi ise owo ni o dara fun won Ise ile kiko (bricklaying), agbe, irohin ati
GEMINI GERMAUX
MAY 23 – JUNE 22
Oruko Irawo yii ni ‘’Gemini’’ omo ti a ba lati May 23 titi de June 22 yoo
je eni ti yoo maa fi igbona okan gba nkan mora sugbon ko ni pe ki nkan naa to
su u, yoo si je eni ti ko ni maa ni ilara. Ire ayo wa fun un, yoo si ni aapon ati
agbara lati se ohun ti inure ba dun si. Awon irawo yii yoo je’a-ri-yawo-ko-
iyale’, won kii si fe gbo alaye afi tiwon saa.
Alaanu ni won, won si lawo pelu. Oniwa rere ni won, won lemi aseyori
ise sugbon ologbon ewe ni won. Ogooro won lo feran awon obi won, won si
laanu won pelu. Ota maa npo fun won lati maa jowu won. Mo ro won ki won
sora lati maa fi inu han ore, ki o ma baa je ota ti n farahan bi ore ni won n fi inu
han.
Won feran lati maa jiyan pupo nitori pe ogbon ti Olorun fun won po,
ogbon ori won nikan ni o pe julo loju ara won. Pupo ninu won je eniyan ti o maa
n mo iwe, ti on ba ran won lowo lati ka a. ko si ibi ti won ko le ka iwe de, pelu
ogbon si ni won maa n se gbogbo nnkan won.
Won je eniyan ti o jafafa ti o si yara pupo sugbon ti won le soro ju Ogbon
ati oye won po to bee ge ti won fi maa n fura si nnkan ijinle tabi ti o farasin si
kolofin ju bi awon irawo yoku ti le mo lo. Irawo ti o si n joba won ni Mercury.
Won je eniyan ti o maa n ko irin meji bona leekan soso. Won si feran
nnkan mejimeji lati maa se ati pe ise kan soso kii wu won afi ki won se nnkan
IKILO : Iwo omoge Gemini, sora pelu iwadi ofintoto, nipa gbogbo irinsi olufe
re, e ko ni pe maa ja nipa sise eleyii. Iwo adelebo Gemini, fi idi mo ile okore, ma
se maa yo fofo jade nigba gbogbo. Ikilo kan naa yii ti o wa fun obinrin Gemini
oun naa lo wa fun okunrin won.
Owu jije lona ti o ga ati ife lati saa mo gbogbo idi abajo saa, lo n fa nnkan
wonyii sehin. Ko si le je ki inu didun wa ninu ile. Gbogbo igbesi aye won maa n
kun fun wahala ati ibanuje miiran sugbon gbogbo re ni Oluwa yoo so di petele.
Bi awon ota n daamu yin, Oluwa ni ki e maa gbadura si, maa se adura ni gbogbo
igba, e ma si se dake adura nigba gbogbo, sora, e ma lo si ile babalawo nitori
kadara re ko fe nkan dudu, e sora fun eleyii. Adura ni oro yin gba.
ILERA : Aisan ti yoo fe maa se won ni lakuregbe, ara riro, otutu, ehin didun, inu
rirun, ju gbogbo re lo ki won sora nitori ibu sisu ati ipalara, eyi yoo le mu ailera
wa fun won.
CANCER CANCER
JUNE 23- JULY 23
Oruko irawo akoko yii ni ’’Cancer’’ omo ti a ba bi lati June 23 titi de July
23 yoo je obododo, omo ti a gbodo mojuto daradara lati igba ewe re. Ki a to o si
ona rere ki o le wulo ni igbesi aye re re. Awon irawo yii yoo je eni ti opolopo
eniyan yoo feran ti won yoo si maa tele ti ko ba fi iwa le won sa. Won yoo feran
orin ati pe yoo je alaisiki eniyan. Won ni opolo pipe fun iwe nuka, won maa n
mo iwe sugbon ere maa npoju fun won ti won ko ba ri eni mojuto won. Won yoo
je olofofo eda ati alayojuran sugbon sa, won je alannu eda.
Gege bi oga (alagemo) n se, ni won o maa saaba gba awo awon elomiiran
wo, ti won o si maa gbiyanju lati se e bi tiwon. Ihuwasi yii je eyi ti o ran ni lowo
pupo, paapaa julo, bi awon eniyan ti n ba keegbe ba je eni Olorun ati ologbon
eda, won o je eniyan ti o sora re pupo, ko si ni ni iwa afojudi si eni keni Bakan
naa, won korira iyipada ati aisimi sibi nigba gbogbo.
Eyi ti agbara won ba ka ni won yoo se fun eni ti won ba feran lowo. Won
feran imototo nibi kibi ti won ba wa, won maa nsaaba je oga ile ise nla, won si je
olusi na sugbon won je eni kii pe binu, kii si pe ki o to tan ninu won. Won feran
awon ebi won, won si ni ese lati maa wa awon ebi. Won feran oro siso, funra
won ni oro inu won a si ma dun sugbon nigba ti o ba di ale, inu won maa n baje
fun ironu.
ILERA : Bi ooru ba mu pupo nigba gbogbo yoo maa ko aisan iba ba won, nkan
gbigbona koba won lara mu. Won gbodo maa gbe nibi ti afefe wa, aisan inu
rirun, ori fifo, orikeerikee ara riro ati ehin didun ko jinna si won.
ISE : Oja tita lorisirisi ona, nkan oso ile ati ti ara, tita ounje, eja, oti eleridodo
(Mineral), onisegun oyinbo (doctor) ati gbogbo ise ti o ba ti omi lo tabi ti a fi
omi se bi ipara oloorun didun (perfume), ikunra oniyebiye (make up), nkan
itowo-to-te (paints) ati beebee lo.
LEO Lion
JULY 24- AUGUST 23
Awon omo ti a ba bi lati July 24 titi de August 23 yoo je olododo ati
oninu-fufu eniyan, won yoo si tete man ka esun si eniyan lese. Ohun kan ti ko
nilaari ni won yoo maa tori re binu nigba miiran. Sugbon oro kii pe tan ninu
won. Bi o tile je pe eniyan nla ti yoo si de ipo giga ni won, sibesibe won yoo ni
emi idariji, oloriire ni won, won, o si ni ore pupo pelu. Kinniun ti a fi se amin
Irawo won yii naa lo si je oba awon eranke. Bakan naa ewe, Wura (Gold) ni
ohun oso fun irawo won yii, oun si ni irin ti o niye lori julo, ookan (01) si tun ni
nomba won, eyi tii se asiwaju gbogbo awon nomba.
Won je eniyan kan ti won se pataki, ti won lagbara, ti won si je alariya.
Iwa ati iseda won yoo je eyi ti o maa n tan imole si ona awon elomiiran, ti o si
maa n se atokun ayo ati inu didun. Bayii naa ni won gbodo maa gbiyanju lati
maa mu aye ati inu didun wa sinu ohunkohun ti won ba lowo si. Won je eniyan
ti a ko ka si pataki pupo laarin awon egbe ati ogba won, igba pupo ni ogo tiwon
yoo si maa bo ti awon elegbe won mole.
Bi o tile je pe awon eniyan wonyii yoo ni owo ati oro pupo, sibe won yoo
si maa ranti alani, ti nwon yoo jo ara won loju ; inakuna ko si jinnasi won lai ro
ehin ola pe bi onii ti ri, ola le maa ri bee. Won feran ise agbara, won kii jeun
lakoko, arè won si maa n le.
Won yoo tete lowo nigba ewe won eyi kii je ki awon irawo yii toju owo
naa, sugbon ninu won, eyi ti ko ba toju owo fun ojo ale maa n ba ara won nibi ti
won ko fe eleyii si le fa ibanuji pupo fun won. Ni tooto, won feran ariya sise,
afefeyeye, ati se-a-ri-mi ninu ohun gbogbo, sugbon o maa n fa ota pupo ba won
awon gan-an maa tun fi eniyan se eleya.
Olooto eniyan ni won, won si tuwoka pupopupo, sugbon iwa bi ti omode
kii saaba kuro ninu ise won titi di ojo ogbo tabi ojo iku, eniyan ti ijade re jo ni
loju ti o si dabi oba tabi ijoye kan pataki ni igba gbogbo ni won, won si feran lati
maa ba eniyan se awada tabi efe titi won o fi darugbo.
IKILO : Mo feran yin leti owe kan ti o wi pe ‘’igberaga lo n siwaju iparun’’ idi
eyi nipe igberaga ni o buru julo ninu iwa aleebu re, lehin naa, o ni lati gbiyanju
lati bori iwa ole ati fifi nkan ti o ye ki o se loni di ojo miiran, iwa ijora-eni-loju a
maa di orikunkun ati aigboran. Faari aseju a si maa di ogo-asan, ma gbiyanju lati
lo agbara ajulo lori eni keni, o le iwa imo-tara-eni-nikan.
Gbogbo iwa wonyii ko le mu iranlowo kan wa fun o bi ko se pe ki o so o
di alabuku, ki o si fa isubu tabi iparun patapata ba o sora pelu awon iwa aleebu
wonyii, ma si sefi ikanju lo ile aye. Ma se fi eni ti o ba wa ninu isoro ati ibanuje
ILERA : Aisan oju, iba, ara riro, ori fifo, iko ati inu rirun wopo fun won. Ju
gbogbo re jo, oju didun ni o se pataki fun won.
ISE: Ise ti o dara fun won niwonyii: Ise Imo Ero lorisirisi ona ( Engineering),
Electiriki,, Hoteeli, Owo, Akowe oja, Akowe ijoba. Agbe sise, Adie sinsin,
Oluko, Orin kiko ati isiro Owo (Accountanney)
VIRGO Vierge
AUGUST 24- SEPTEMBER 22
Oruko Irawo akoko yii ni ‘’Virgo’’ Omo ti a ba bi lati August 24 titi de
September 22 yoo je eni ti o le sise pupo, yoo si ni itara si ise ti won ba dawole
lati se. Awon eni naa yoo je olooto ati olufokansin, eni ti ori re yoo ya si iwa
Nigba miiran eewe, won yoo huwa ti o yato si iwa won tele ati nigba miiran,
won yoo dake so ohun ti ko ye ki won dake si. Awon eniyan wonyii yoo feran
awon ebi won lopolopo, won yoo si feran lati maa ran awon omo won lowo ninu
eko won lati le je eniyan nla lolo ola. Gbogbo ipa ni won maa n sa fun awon
omo won, won si feran lati se koriya fun ise ile Olorun. Ni akotan, won feran lati
maa josin ni ile Olorun.
ILERA : Inu rirun, ara riro, eforie, ehun didun ati eje riru a maa saaba se won.
LEBRA
SEPTEMBER 24 - OCTOBER 22
Oruko irawo yii ni ‘Libra’ Omo ti a ba lati September 24 titi de October
23 yoo je eni ti suuru re po ti kii si tete binu. Omo ti o see ba da nkan po, yoo je
alaanu eniyan fun obi ati eniyan gbogbo pelu. Won yoo si je onidajo ododo, yoo
si feran aso wiwo ati oso sise. Won a maa se orikunkun si gbogbo nkan, won je
eni ti won maa o puro nkan ti won ko se . Won si gbodo maa sora fun iwa won,
ki awon eniyan ma baa mu won ni ota. Ki won maa sora nipa oro ogun ki o maa
lofa ota ba won. Abuda won je eyi ti o tu ni lara, won si je eni ti o saaba maa
rerin muse, itura ati anfaani nlanlaa ni yoo je lati maa bai ru won kegbe. Olorun
fun won ni ebun oju-ona pupo, eyi je ki won tayo elegbe won, ti won maa saaba
je oga ninu ise ona sise. Won je eniyan ti maa n fe irepo ati alafia nigba gbogbo
eyi yoo si mu ki awon eniyan feran lati ba won sore. Bakan naa, won je eniyan ti
o ni ogbon éwé paapaa julo iru eyi ti eniyan le ti owo re le te ohun ti o nfe lai fi
agbara tabi ja se e.
Won je eniyan ti won kii fe farada isoro ti o ba de ba won ati pe won tile
ni ehun iyebiye lati tete maa gba kaamu ninu ipko kipko tabi isele ti o ba de ba
won. Won si tun ni imoran lati maa fa elomiran yo ninu iwa buburu ati rudu
rudu. Won a si maa feran lati maa be elomiran kegbe, ajorinpo je iwa ti o jinle
ninu iwa won pupo, won si feran lati maa wo aso daradara. Won je eniyan ti o ni
arojinle ti o si tete n fi oju-inu wo nkan pupo. Nigba miran, o seese ki won mo
ohun ti o wa ni okan elomiiran tabi ohun ti o seese ki o sele lori oro kan. Won
korira iwa ika, ko si si ohun naa ti o le mu won ba eni ti o ba huwa ibi gbe po.
ISE : Won ko ni fe duro nibi ise kan, eyi si le je ohun ti o le re won sile. Ise
oluko (tescher), oniwaasu, adajo, oselu, agbe ati nkan esin dara fun won.
IKILO: Ma se kuro mibikan lainidi Kan pato. Maa toju ohunkohun tii se tire,
ma se faaji laisi ise, ki o si maa wo aso ti o dara ti o siba o lara mu. Kun fun
SCORPION Scorpion
OCTOBER 23- NOVEMBER 22
Oruko irawo akoko yii ni “Omo ti a ba bi lati October 23 titi de November
22 yoo je eni ti o ntenumo oro ti o ba fe, yoo si so o di ija bi eniyan ko ba gba
tiwon, won yoo tun je olokan lile ati alagidi eda, bi ohun kan ba mu won binu,
kiki asoju oro ni saa.
Eni naa yoo je eni ti o feran ki won maa yin oun fun aseyori yowu ti oun
ba se, iro pipa ki yoo si ninu iwa won bi o ti wu o kere mo, yoo si feran afarawe,
sugbon eleyii maa n ko ba won. Bi ibinu won ba de, won yoo si feran otito siso.
Iru eni bee yoo feran lati maa fi owo pamo ti eni kakan ko le mo nipa re, a si
maa ro ehin, ologbon omo ni yoo je, yoo si mo iwe ti eniyan ba to o ni ile iwe.
Won yoo je osonu, alagidi ati onroro eniyan, won yoo maa paro nigba
miran, won je onibinu eda ti okan won maa nru, nigba miran, ko ni bikita lati
maa fi agidi se nkan, nkan si maa njo won loju to be ge. Eniyan to ni igboya ni
won, nitori idi eyi ni won maa n fi agidi se nkan. Alakikanju eniyan ni won lenu
ise, won je eniyan ti won maa npa asiri mo pupo. Dajudaju, won je eniyan ti
won maa nse ayewo okan si rere, eyi ti o si jo ni loju nipa abuda won ni wi pe.
Yoo je eniyan ti okan re duro gboningbonin nipa ona yowu ti o ba te si ati
lori ohunkohun ti o ba ni igbagbo ninu re ti o si faramo. Nihin yii sa, idaru okan
le maa saaba wa fun un nitori pe iwa miran tu nbe ninu re ti o lodi si iwa
idurosinsin ti mo wi yii. Idi eyi ni pe labe ase omi ni irawo yii wa ; gege bi iwo
naa si ti mo pe omi ko duro ni oju kan soso bi kose ki o maa san sotun ati sosi
tabi isoro lati se ipinnu kan pato lori ohun kan.
IKILO: Sora fun iwa agidi, inu-abiju, nini ipamora, orikunkun ati ai fe gba
imoran elomiran. Iwa esan gbigba lara eni to ba se ni ati igberaga, awon
nkan wonyi ko dara, gbiyanju lati ko ara reni ijanu lori awon iwa naa.
Pa ahon re mo gidigidi ki o ma se soro ti o le pa eniyan lara. Bi
kadara ko tile fe fi ojurere wo eniyan, o seese ki Oluwa ran e lowo nipa iwa
rere. Sora fun iwa agbere nitori ki o ma ba kadara re je, eniyan le ko arun
nipa isekuse.
ILERA : Aisan ti o maa n yo won lenu ni iba, efori, ara riro nigba miiran, aisan
won ko po ju eyi lo, ofowofa le da kun aisan won nipa isekuse. Won lojo aisan ti
ara won ko ba da
ISE : Ise ti o dara fun won ju ni ise ise Noosi (Nurse) aso ofi hihun, egbogi tita
oluko, orun kiko, ise oko oju omi, won a ti feran ise agbe sisis pelu.
Sagittarius Sagitaire
NOVEMBER 23 – DECEMBER 22
Oruko irawo akoko yii ni “Sagittarius” Omo ti a bi lati Nov 23 titi de
December 22 yoo je olorire, gbajumo, olokiki ati akikanju ; eni ti o laayan ninu
ohun gbogbo. Ero rere ni ero won nigba gbogbo, ohun rere ti won nlepa ki yoo
sai to won lowo. Oninufufu ni won nigba miiran sugbon won yoo se bi eni ti ko
ka nkan si to bee ge bi won ba pinnu lati se ohun kan, won kii gba imoran.
Won ko ni fe dasi oro ti kii se tiwon. Irin ajO lilo ni won yoo yan laayo,
idale se anfaani fun won, won ko ni fe ka eniyan si gege bi eni ti o le se nkan
dara bi tire. Nigba miiran ohun kekere ni yoo so di ibinu ti yoo si ka a si ese si
onitohun lorun, sugbon ibinu re ko ni maa pe rara, ko si le di oro sinu pelu. Iru
awon omo bayii ko nii fe ki eni kan je gaba le awon lori tabi je alase fun won.
Won ko si ni fe lati ba elomiiran da ise po rara.
Ebun titayo ni eleda fun won, eyi ti ko fe je ki won o beru eni Kankan afi
eni ti o ba bu ola fun won, eni ti yoo ko eniyan mora ni won, eyi yoo si je ki won
ni ore pupo, won yoo si fe tete gbe iyawo pelu ikanju. Eleyii ni yoo je ki won
maa ko iyawo sile tabi to ba je obinrin ni, yoo maa ko oko sile. Won a si maa ni
oko pupo nitori won ko ni ni itelorun, suuru, ifarada ati iteriba.
Won a maa ni ikanju si gbogbo nkan, emi igberaga a poju won lo, won a
si feran lati maa fi ise kan sile se omiiran ; eyi ko si ni je ki gbogbo re ye won.
Alaanu, alagidi, olorikunkun ati eni ti o kundun ounje ni won, koda, won le fi
owo meweewa jeun paapaa.
Won maa n wa ota fun ara won nipa iwa kiigbo-kiigba ati eeke eebu, won
a maa jo ara won loju pupo. Won a tete maa wa ipo ola fun ara won lai le de ipo
naa. Obinrin won ko ni fe gbe ile oko, bee ni okunrin won a feran obinrin.
Igberaga ati okan-ile po ju fun won, won si feran lati maa se ise asekara.
ISE : Awon ise ti o dara fun won ni ise iwaasu. Asiwaju esin Olorun, ise
agbejoro (layer), oluko, oselu, agbe sise ati ise ti o le mu ki eniyan maa lo kiri
laarin opo eniyan.
CAPRICON
DECEMBER 23- JANUARY 20
Oruko irawo akoko yii ni “Capricon” Omo ti a bi lati December 23 titi de
January 20, yoo je eni ti yoo ma se nkan Pataki. Oro die ni yoo maa dun won,
onitiji eniyan ni won, won ko ni nfe maa yoju si nkan ti ko kan won tabi nkan
onikan; oninu rere eda si ni won pelu. Ojo aye won, ni owuro yoo kun fun
wahala ati isoro sugbon nigba ti o ba di asale ni gbogbo igbesi aye won yoo wa
maa dun yungba ti yoo si toro minimini bi omi a fowuro pon.
Won je eniyan ti a fun ni ebun ogbon ati oye lopolopo, ohun gbogbo ti o
ba si je mo ti emi tabi ifarasin, ni okan won yoo maa fa si. Eniyan ti o se pataki
ti o si lagbara pupo, ni won je, okan won yoo le lori ohun ti won ba fe tabi eyi ti
won ko fe.
Won ko ni tete lowo titi yoo fi de idaji ojo aye won. Igbesi aye won kun
fun wahala ati idaamu ni igba ewe won ; yoo dabi pe aye su won. Bi o tile je pe
laasigbo po fun won ni ibere. Aseyori won a wa fi ara han lati omo ogoji odun
tabi o le die ni gbogbo nkan yoo maa bere si ddara fun won.
Nitori iya ti won ti je yii, won a maa toju gbogbo nkan ti won ni. Eni ti
Olorun ba ran won si ni won yoo maa se loore, kii se pe iyan sa oogun gba nkan
lowo, sugbon won ko fe alaseju eniyan, won hawo die, nkan kii pe su won, ti
gbogbo eni won ba se loore ko ba dupe, to je ibi ni won fi su won, iru eni bee kii
ILERA : Aisan won ni eti didun, efori, jedijedi, lakuregbe, giri, kuruna, ehin
didun. Eje riru le gba ona eburu wole ti won ba nronu pupo, ki won maa sora
nitori ifarapa, eleyii ko si fa ipaya rara. Ki won saa maa gbadura, Oluwa yoo
daabo bo won bi o tile je pe oniruuru aisan ara po fun won. ISE : Awon ise ti o
dara fun won ni owo, mekaniki (mechanie) iwe kika, ise ti o pa eniyan lokan po,
ti ko ni je ki eniyan ronu. Owo moto, ise tete kii se ona won. Ise titan kan adura,
adajo, agbejoro, owo alajapa ( ki won ra oja ni ilu kan lo si ekeji) ati ki won maa
se ere tiata ( theatre) lokunrin ati lobinrin.
IGBEYAWO : Capricon, Taurus, Virgo ati irawo miiran pelu adura ati suuru. Ile
ati Yanrin ni a fi se eda won. Ojo ti o dara fun won julo ni ojo Monday. Awo ti
o si ba won lara mu ni awo eweko (green) ati pupa resuresu (pink). Nomba oriire
won niyii : 1, 3, 8, 17 ati 26. Pool tabi loto ti won ba n ta.
ILERA: Awon aisan wonyii ni yoo fe maa se won: aran; eje ruru; ara wiwo,
ooyi-oju, ara riro ni keerikee, etori, lakuregbe ati oju didun. Nigba n won ba de
idaji igbesi aye won, ki won sora fun awon aisan wonyii ki won ma baa bori
won. ISE: Ise ti o dara fun won niwonyii: Noosi, aso reran, Dokita, owo sise
egbogi tita, ise ina, akowe ati egbe.
ILERA: Aisan bi iba, otutu, efori ati aya didun ni yoo maa se won nigba ewe
tabi ti won ba ni omo owo.
ISE: Awon ise wonyii dara fun won, ise akowe, oti sise ati tita, oko oju irin, oko
oju omi, egbogi pipo (pharmacy), ojise Olurun, owo sise tabi ki won da ile ise
sile, oluka ati awon iseti o pa eniyan lokan po.
1-Ti obinrin ba loyun, ti o ba hun iwakiwa tabi fewo, eleyii fi han gbangba pe
emo naa yoo maa jale ni aye re. Nigba ti Olorun da Adamu ati Efa saye tan, ti
won si ti se ni kadara bubru nti wo inu aye omo eda. Iwa buburu ni Efa fi bi
keni, lo fi ya apaniyan, ohun ti eniyan ba hu ni iwa ni yoo je kadara re.
2- Awon obi omo miiran wa ti o je pe kiki ija tabi ki won maa gbe omo ara won
sepe lasiko oyun ati nigbakungba, o daju gbangba pe ipin ija ati epe ni won maa
yan fun omo won.
3- Ogunlogo abiyamo ti fi iwa buburu bimo sile, iwa buburu naa lomo won yoo
si maa nhu. Ko sadede ri bee, kadara iwa buburu ti won yan fun won ni.
4- Awon kadara ti omo ti ba pade lati inu eje lasiko oyun, awon wonyii le pupo
ninu aye omo eda lati yipada. Afi Oluwa nikan lo le yii pada nitori pe Olurun
nikan lo ni isegun ti o le wo iponju san.
1- Bi obinrin ba n se nnkan osu tabi ri alejo re, ko gbodo je ki aso naa maa fi
ara kan ogiri tabi iganna. Bi o ba n se bee bi osu naa ba pari, ti ohun pelu
okore si lopo, ti osu naa ba duro lara re, ogiri ni yoo wo pa omo naa bi
won ba bi i.
2- Bi obinrin ba loyun ti o balo nsan olo ata lati fi sebe, bi aboyun naa ba nse
be ti a fi omi olo naa se, bi o ba bi omo naa, olo inu tabi osi ko ni je ki
omo naa gbadun ojo aye re.
3- Bi obinrin ba loyun ti omo naa ba je okunrin, nigba ti a ba fe da iwo re, ki
o je deede orunkun ti ko ba de orunkun re, omo naa ko ni le ba obinrin lo
daradara, yoo maa re e ati pelu pe yoo si je eni ti aran yoo maa yo lenu
nigba gbogbo. Bi o ba si tun wa koja orunkun re, yala okunrin ni tabi
obinrin, yoo je okan ninu awon pansaga paraku.
4- Bi obinrin ba n se nnkan osu, ko gbodo fi owo re nu ewe, bi o balo se bee,
lehin ti o ba pari nnkan osu naa, bi oun pelu oko re ba pade tabi lopo ti
osu naa ba si duro si ni lara, iru omo bee lo maa nya ‘’ ko-gbele, ko-gbe-
ta’’, yoo nsi maa hu iwa ipata ati ipanle kiri, ko si le ni ibujoko kan lode
aye re rara, nitori naa ni obinrin se nilati kiyesara.
5- Bi obinrin ati oko re ba pade, ki won ma se je ki aso ti won ba n lo tabi fi
tunrase kan ogiri (wall), bi o bal o fi ara kan ogiri, ti o ba si di oyun, bi
won ba bi omo naa tan, ogiri ni yio wopa iru won.
Gbogbo awon wonyii je akunleyan eda lati ode orun wa, ti oogun, ogede,
aasan tabi ifa ko le yipada.
Akiyesi - Wo igbesi aye Abrahamu ninu Genesis ori Kijilelogun ese keji de
eketala (22 ;2-13).
Mo wi fun yin, eyin omo iya mi ti o ni anfani lati ra iwe yii fun lilo laarin
odede ati ijo eniyan Olorun, ki a ba la mo bi a o se yera fun ewu ti nbe niwaju
wa. Ninu odun kan tii se otaleloodunrun ole marun-uu tabi mefa (365 days
common year and 356 days leap year), ojo merindinla dorin to buru ju ninu osu
kokan
1- Bi eniyan ba se igbeyawo ni okan ninu awon ojo naa, ija, iponju ati
wahala lo maa nje fun won, leke gbogbo re, ituka ni yoo gbehin re afi epe
durs.
2- Bi eniyan ba bere ile kiko ni okan ninu awon ojo naa, orisirisi idanwo ni
yoo ba pade. Bakan naa, ki eni keni ma se gbin ohun ogbin laarin re ki o
ma baa dabi eni pe omulemofo ni yoo jasi ni igba ikore. Bi onitohun ba
tile sesi ri nnkan ta ninu nnkan ogbin naa, afaimo kio ma fi wo aisan.
3- Bi eniyan ba bere irin-ajo oju omi ni okan ninu awon ojo wonyii, aisan ni
iru eni bee maa nba bo tabi ki jamba se e.
4- Bi aisan ba kolu eniyan ni okan ninu awon ojo naa, ti opolopo lo njasi iku,
etahoro lo maa nru u la.
5- Bi won ba si bi omo kan ninu ojo wonyii, yoo maa je alailera nigba
gbogbo ati pelu kii se eni ti emi re le gun to bee, ju bee lo.
6- Mo si tun fi ye pe, bi awon ojo yii ti buru to nni, awon okan wa to buru
julo ninu won, eyi tie mi ko fe ki eyin omo iya mi ninu Olorun se aigbaran
si rara. Awon ojo naa niyii; March 3, August 17 ati September 1, 2, 30.
Awon ojo maraarun yii ko dara.
7- Awon ojo to buru ju gbogbo re ninu awon ojo naa ati ohun ti o sele lojo
naa ni wonyii: (i) April 1, eyi ni ojo ti won bi Judasi Iskariotu ti ise
onikupani. (ii) Bakan naa ni osu August 1, ojo naa gan-an ni won le esu ti
Bi eniyan ba pa nnkan tabi ta eje sile ni okan ninu awon ojo meteeta yii,
oluwa re yio ku ki atori ojo meje tabi mejo. Omo ti won ba si bi ninu awon ojo
meteeta yii yoo ku iku ojiji, yoo si je eni egan, ètè, alabuku ki o to fi aye sile.
Akiyesi nla niyii fun eyin omo iya wa, ohun kohun yio wu a ba ni ki eniyan ma
se, ki o ma se fi”aya-koko-inaki” se e rara. Iwe owe ori kejilelogun, ese keta
Owe 22:
O so bayii pe, Ologbon eniyan ti ri ibi tele, o si pa ara re mo, sugbon
awon ope koja, a si je won niya. Nitori naa, e je ki oro inu iwe yii ye yin
yekeyeke.
2- OJO MONDAY
Omo ti a ba bi ni ojo Monday ki yoo si ilosiwaju deede fun un ninu
idawole re ni ibere aye re bi o ti nfe, sugbon yoo je onirele ati oninurere to
bee ti awon eniyan yoo fi maa re e je, sugbon nipa ebe ati adura, igbehin
re yoo wa dara ju ti isaaju lo.
3- OJO TUESDAY
Omo ti a ba bi ni ojo Tuesday yoo je omo lile ati oninu fufu. Bi o ba se
okunrin ni, yoo feran lati maa se ijangbon. Ti awon obi re ko ba tete mura
si oro re, yoo ko wahala ba won nipa iwa ati ise re, o le fa ijiya nla tabi
iku ojiji ba ara re paapaa.
4- OJO WEDNESDAY
Omo ti a ba bi ojo Wednesday yoo je omo lile ati olori aseta. Bi a fi si ile-
eko, yoo ni imo pupo, yoo si je olokiki ni igbesi aye re. Ise ko ni o dara
fun iru won julo.
5- OJO THUNDAY
Omo ti a ba bi ojo Thunday y o ni aisiki, ayo ati alaafia won daradra.
Olola ati oloro ni yoo je ni igbesi aye re. Onigboya ni won, sugbon ota
6- OJO FRIDAY
Omo ti a ba bi ojo Friday yoo je alagidi, onijangbon ati oloriire, opuro ati
oloro pupopupo.”A-baya-ko-bi-aara” ni won, won ki yoo dide fun egbe
won jokoo, bee ni won ki yoo ri isoro ni ojo aye won.
7- OJO SATUDAY
Omo ti a ba bi ojo Satuday yoo ri idanwo ati ibanuje die ni ibere ojo aye
re. Gbogbo igba ni yoo maa se si ofin, yoo si maa jiya sugbon ni ikehin,
yoo di olufokansin ati eniyan Olorun. Awon egbe ati agba ti o ju u lo yoo
maa bu ola fun un, Oluwa yoo bukun fun nigbehin aye re, yoo si wa di
olola ati oloro nla ni opin aye re.
Nitori naa, eyin ara mi, e ma se wo oko a nda ifa tabi opele, ko si ere
kankan nibe, Oluwa fi i si wa lokan lati se eyi fun eyin omo iya wa ninu
Oluwa, lati kiyesara ati lati fi Olorun se igbekele yin.