You are on page 1of 1

26th March, 2023

Ekunwo Isuwona III


Genesisi 1: 27 – 28.

Awon igbese ti a fi n so awon ala, iran ati ero ti a n ri gba lati odo Olorun di nnkan to wulo to si niye owo lori ni a mo si
ise. A le se ise lorisirisi ipele lati mu orisirisi iye jade. Iye to ga maa n mu owo to po jade. Bakan naa, bi awon igbese ise
wa se dara si ni awon isura ti a maa ri nibe yoo se po si. Bi a ti n se ise wa, a gbodo maa ranti pe ninu aye to n subu lo ni a
n gbe , awon eto ti a fi n gbe inu re ko pe. Nitori idi eyi, a n ba awon eniyan pade tabi ipo to n fe pin wa lemii lori awon
ohun ti a n se to si fe din iye to wa lori awon ohun ti a n se ku. Nipase ogbon Emi Mimo, awon idojuko to n dun koko
mo isise wa nibi ise wa tabi nibi okowo wa le di ona fun wa lati dagba gege bi Jakobu ti so agbo eran egbon mana re
Labani. Awa onigbagbo le gbara le iranlowo Olorun lati mu ki ise wa dara si, ka si yi awon ipo to soro si awon anfani
lati gbooro si (Genesisi 30: 37 – 43; Genesisi 31: 4 – 12). Iwoye ikekoo wa toni da lori bi a se maa gbajumo sise ise lati le
se aseyori ni ti ekunwo isuwona.

IJIRORO

1. Bawo ni o se le mu ipa re dagba si lati maa gba ju iye owo ti o n gba lowo lo ?
2. Bibeli wipe, « Bi irin ba kuju, ti on ko si pon oju re, nje ki on ki o fi agbara si i ; sugbon ere ogbon ni fi ona han
»(Oniwasu 10 : 10). Dida agbara po mo ise yoo ran wa lowo lati le fun omoniyan ni iye to po, ka si fi nipa bee mu
awon isuwona to n bo sodo wa po si. Awon ona niyi lati fi gba owo ni ipele to po :
Fi akoko re sowo. Akoko je ohun isura to niye lori ti a le so di owo oya. Nitori naa, o se pataki ka to awon ohun
ti a fe se bi won se se pataki si lati le sa fun fifi akoko sofo. Owe 14 : 23 ; Owe 12 : 11.
Ta oja ati ise sise. Se ohun kan ti yoo ba aini kan pade ti awon eniyan yoo fe lati sanwo fun. II Awon oba 4 : 7;
Owe 31: 24.
Lo anfani ipa awon eniyan miran nipa gbigbe eto kale ati kiko awon eniyan jo lati sise papo. Eksodu 18: 17 –
21; Oniwasu 9: 12; Owe 22: 17.
Mu ki owo re maa sise fun e. Se idokowo lori awon ohun ti yoo mu owo wole fun e. Genesisi 41: 34 -36;
Oniwasu 11: 2.

Ona to dara lati fi ara re si ipo lati ri anfani awon ise to le mu ekunwo isuwona wa ni lati je eni to setan ni gbogbo igba
lati sise tabi bukun awon elomiran. O le je lati gba won ni imoran, kopa nipa ise tabi imo tati mu ohun kan sele, fi ona
abayo han enikan to n wa ona abayo, abi yonda ara re fun iranlowo to ba nilo. Moomo se eyi pelu okan to mo . Iru
nnkan bayii ko ni mu ipa re nikan gbooro si amo,bakan naa, o le si awon ilekun ti o ko mo pe o wa nibe tele. Nibi ti a ti
n ran awon elomiran lowo, Olorun le fun wa ni awon ero titun fun ibi itaja bi o ti n teti si Emi Mimo. Waa se aseyori
loruko Jesu. Amin.

You might also like