You are on page 1of 52

ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN SS2

YORUBA LANGUAGE
OSE AKORI EKO
1 EDE – Atunyewo lori Aroko ajemo isipaya:
i. Ilana ero aroko ajemo isipaya
ii. Akole, Ifaara, koko oro, agbalo gbdo
iii. Alaye kikun lori eto ipin afo
iv. Kiko aroko lori akole bii Omi, Iyan,Oja ati bee lo
ASA – Atunyewo lori eko ile:
i. Ibowofagba, ikini, bi o se ye ni gbogbo igba, suuru, otito sise, iforiti,
igboran ati bee bee lo
LITIRESO – Itupale asayan iwe ti ajo WAEC/NECO yan ti rgbe Akomolede fi owo
si.
2 EDE – Atunyewo lori silebu ede Yoruba:
i. Oriki silebu
ii. Silebu oni faweli kan (F)
iii. Silebu alakanpo konsonanti ati faweli
iv. Pipin oro si silebu
ASA – Atunyewo ise abinibi:
i. Ise agbe, gege bi ise abinibi gbogbo wa. Awon ohun elo ise agbe:
Oko, Ada, ati bee bee lo
ii. Ise agbede, ise alapata, ise akope ati ise gbenagbena ati bee bee lo
LITIRESO – Itesiwaju lori atupale awon iwe Litireso:
i. Awon eda itan
ii. Ibudo itan
3 EDE – Atunyewo aroko onisorongbesi:
i. Alaye lori oro onisorongbesi
ii. Kiko aroko onisorongbesi to dale isele awujo
ASA – Ona ibanisoro:
i. Lilo awon eya ara fun ibanisoro bii sise ni ni eekanna, ori
gbongbon, oju sise, ara mimi, titenimole, imu yinyin ati iparoko.
LITIRESO – Itupale iwe litireso:
Ahunpo itan ati awon asa Yoruba to seyo ninu itan naa
4 EDE – Atunyewo ihun oro
i. Siseda oro rouko
ii. Alaye lori awon oro oruko ti a ko seda sugbon ti won dabi eyi ti
aseda bi ile, oba, omo, iay ati bee bee lo
ASA – Itesiwaju eko lori ona ibanisoro:
i. Ibanisoro ni aye ode oni bi iwe iroyin, telifonu, redio, foonu, foonu
alagbekaa 1 meeli ati fasi (fax)
LITIRESO – Sise atupale asayan iwe litireso:
i. Awon ilo ede/Akanlo ede
ii. Sise orinkinniwin won
5 EDE – Onka Yoruba:
i. Lati egbaa de oke meedogbon on (2,000 – 500,000)
ASA – Awon orisa ile Yoruba:
i. Ogun, Obatala, Esu
ii. Awon ohun ti a fi n bo eon ati oriki okookan won
LITIRESO – Kika iwe asayan ti ijoba yan
6 EDE – Onka Yoruba:
i. Lati oke meedogbon on de Aadota (500,000 – 1,000,000)
ASA – Awon orisa ile Yoruba ati bi a se n bo won:
i. Orunmila, Sango
ii. Awon ohun ti a fi n bo won ati oriki okookan won
LITIRESO – Kika sayan iwe litereso Yoruba ti ajo WAEC/NECO yan
7 EDE – Atunyewo awon eya ara ifo:
i. Lilo awon eya ara ifo
ii. Alaye lori afipe asunsi ati afipe akanmole
ASA – Awon orisa ati bi a se n bo won:
i. Awon orisa miiran ni agbegbe awon akeeko
ii. Ipo orisa ni ile Yourba
iii. Pataki orisa lawujo Yoruba
LITIRESO – Kika iwe litireso Yoruba ti ijoba yan
8 EDE – Atunyewo awon iro ninu ede Yoruba:
i. Iro faweli, iro konsonanti ati iro ohun
ASA – Ero ati igbagbo awon Yoruba lori Oso ati Aje:
i. Ise ti awon aje n se ninu isegun ati iwosan
LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan
9. EDE – Atunyewo apejuwe iro konsonanti ati iro faweli:
i. Yiya ate faweli ati konsonanti
ii. Sise apejuwe awon iro konsonanti ati faweli leyo kookan
ASA – Ero ati igbagbo Yoruba lori akudaaya ati abami eda:
i. Akudaaya ati abami eda bii Egbere, Iwin, Alujonu, Ebora ati bee
bee lo
LITIRESO – Kikai we litireso ti ijoba yan
10 EDE – Atunyewo eko lori ami ohun:
i. Kiko ami ohun Yoruba meteeta
ii. Alaye lori ise ti ami ohun n se ninu ede Yoruba
ASA – Igbagbo Yoruba nipa ori tabi eleeda:
LITIRESO – Kika iwe litireso Yoruba ti ijoba yan fun saa yi
11 & 12 Atunyewo lori gbogbo ise saa yii ati idanwo ipari saa keta lori Ede, Asa ati
Litireso ede Yoruba
OSE KINNI

AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA


Aroko ajomo-sispaya je aroko ti a fi n se isipaya awon ori oro to je mo ohun ayika eni. Aroko
yii fi ara jo aroko asapejuwe sugbon o jinle ju u lo. Bi aroko asapejuwe se le fe ki o sapajuwe
‘Ile-iwe re’, aroko ajemo isipaya yoo fe ki a so nipa idagbasoke to de ba gbogbo nnkan ile
iwe naa titi de ori eto isakoso. Aroko ajemo isipaya maa n tu isu de idi ikoko ijinle itumo,
anfaani ati aleebu ori oro.

Eyi tumo sip e aoko ajemo isipaya pe fun imo to gbooro nipa sisafihan bi nnkan won se ri
tabi sise. Ki akekoo to le yege ninu aroko ajemo isipaya, o gbodo nifee si ise iwadii nipa
nnkan ayika, ki o si ma aka orisirisii iwe, jona ati iwe-iroyin, ti yoo fun un ni imo kikun nipa
nnkan ayika.

Aroko ajemo isipaya le je eleyo-oro tabi apola ti won ni itumo to jinle. Apeere aroko ajemo
isipaya ni:

(i) Omi
(ii) Iwe iroyin
(iii) Ise Tisa
(iv) Oge-Sise
(v) Imototo
(vi) Aso ebi

Aroko ajomo-isipaya tun le je ori-oro bii:

(i) So awon nnkan ti iwo o se ti won bay an o ni alamojuto eto iwosan ni agbegbe re
(ii) Se ekunrere alaye bi iwo yoo se seto ayeye odun ibile laarin awon akekoo ile-iwe
re.

E je ki a ka aroko ajemo isipaya yii wo, bi apeere:

OWO EYIN
Orisirisi iwa ibaje lo maa n fa Orile-Ede seyin. Okan ninu iru awon iwa ibaje bee ni
gbigba ati fifuuni ni owo eyin. Iwa yiiti gbile ni Orile-Ede wa. Bi o tile je pe opo awon eniyan
nla lo wa ni idi iwa yii, sibe eyi ko so di nnkan to dara. Ani ohun ti ko dara ko ni oruko meji,
ko dara ni. Orisirisi oruko ni awon eniyan fun owo-eyin. Awon kan n pe e ni ‘Owo-abetele’.
Awon kan n pe e ni ‘sowo kuduru’. Awon miiran si n pe e ni ‘riba’. ‘Owo ibole’ ni awon kan
mo on si. Oun kan naa ni won n pen i ‘owo pabe’ tabi ‘owo ijule’. A ri awon ti n pe e ni
‘egbo’. Ko si oruko ti a pe ata ti a le mu tita ata kuro. Ani ko si oriki ti a le fun iwa-ibaje yii ti o
le so di nnkan rere.
Ki i se owo nikan ni awon eniyan n lo gege bi abetele. Awon miiran n ra nnkan gege bi ebun,
won o si fi se riba. Bee ni a si ri awon obinrin ti won n fi ara won dipo owo abetele. Ohun ti o
daju ni pe ni gbogbo kolofin awujo wa ni iwa yii ti gbile bi owara ojo. Ko si si eni ti o le gba
riba ti yoo se eto. Bi adajo ba gba a, too gbe ejo are fun elebi.

Olopaa ti o gba a ko ni le mu odaran. Wolewole to ba gba a yoo maa gba iwa idoti laaye
laarin awon eniyan. Oluko to gba a ko ni salaida esi idanwo ru.

Asa awon kan ni pe ko si ibi ti won ki i ti fun ni lebun. Won ni ko si ibi ti iwa yii ko si, won lo
tile wan i ilu awon oyinbo Geesi. Iro patapata gbaa ni eyi. Bi o ba tile wa nibe, eyi ko so di
iwa daradara. Ohun ti won n se ni ohun ni fifi emi imoore han. Bi a ba se enikan lore, yoo si
fun wa ni nnkan ami ope re. Ki i se pe owo la o beere fun nnkan naa. Bee ni ko pon dandan
ki o fun wa. Awa naa maa n se iru eyi ti o wopo loke-okun ni Orile-Ede yii. Gege bi apeere, bi
enikan ba ran wa ni eru, a oo wa nnkan fun un. Bee si ni a maa n fi imoore han fun eni toju
wa ni ile ounje.

Ko si ona ti a gba wo owo ibole ti o so di nnkan rere. O ye ki gbogbo eniyan yera fun iwa
abetele ki Orile-Ede wa le niilosiwaju. Bi a ba yera fun iwa abetele, onikaluku yoo le gba eto
re. A o si fi ogun asa rere titun sile fun awon omo ti yoo ropo wa ni eyin-ola.

ALAYE: Aroko yii ko gun, sugbon o je apeere ajemo isipaya. Bii abuda, ori-oro yii jinle. O
gba ki akeeko ni imo kikun nipa owo eyin. E je ki a woe to aroko yii:

ETO
(i) Ifaara: o sipaya orisii itumo ti ‘Owo eyin’ ni ipin-afo kin-in-ni ati ikeji. Oun yii dara
pupo.
(ii) Koko-Oro: Gbolohun ipari ipin afo keji ati iketa ni ni alaroko ti n so ewu owo eyin
bi o se le dena eto eni si idajo ododo.
(iii) Ikadii: Ikadii aroko yii fi han pe yiyera fun iwa yii lo le mu ilosiwaju ati eto idajo
ododo wa ni awujo

E je ki a tun wo apeere aroko ajemo isipaya yii wo.

OWO
Koseemanii ni owo je fun eda. Owo ni ohun ti a n na tabi fi ra nnkan. Ire meta ni eda n wa ni
ile aye, bi Ifa, elerii-ipin se la a sile. O ni “Ninu gbogbo ire ile aye pata poo, meta l’o se pataki
ju. Awon ire meta naa ni ire owo, ire omo, ire aiku (tabi alaafia) pari iwa.” O ni:

Ire meta l’awa n wa


Awa n wowo o,
Awa n womo,
Awa n wa atunbotan aye.
Ifa ni ‘Eni ti o ba ti ni awon ire meteeta wonyi ti ni iyoku. Eni ti o ba lowo yoo niyawo, yoo
kole, yoo si ni aso. Idi niyi ti owo fi je egbon fun gbogbo ire yooku.’

Owo yii ni awon Yoruba pen i ‘aje, Ogungun-niso’. ‘Owo, apekanuko’. Awon Hausa pe e ni
‘Kudi, eya ibo pe e ni ‘Ego’.

Ni orile ede Naijiria, owo Naira ati Kobo ni a n na. Awon ilu okeere bi ilu Oba n na owo Dola,
orile ede Amerika n na ‘Poun’, bee ni awon orile de agbaye miiran si n na ‘Euro’. Owo ibaa je
dola, poun tabi naira, ‘nina lowo’. Ojuse pataki kan ti a mo on mo niyi. Won eni to ba n nawo
ni a n pe ni ‘nawo-nawo’, alowo-lowo maa lee owo da. O le kole alaruru, o le ra obokun-
oloye, o le fe iyawo. Owo ni a fi n se ohun gbogbo. Awon ayan a maa lulu pe “Olowo sehun
gbogbo tan, iya ni o je omo talika”. Gbajumo olorin kan tile tusu de idi ape ninu orin re yii:

“Ohun gbogbo t’Oluwa o se fun wa,


Ma j’owo o gbehin rara
Tori oro t’owo ba se ti
Ile lo n gbe
E wa wohun t’owo se o
Nile aye ta wa yii
Owo ni n se nnkan ‘re
Owo ni n se nnkan gidi
Edumare fun mi ni ‘Moni’ o
Ki n r’owo fi jaye.”
Bi owo se se pataki to, tolori telemu ni n wa a kiri. Kaakiri agbaye ni awon eniyan ti n sare
owo. Won ni “Ohun ta o sonu ti gbogbo wa n wa kiri”. Ona kan gboogi to mo ti a fi le ri owo
ni ki a tepa mose nitori ‘Oju boro ko ni a fi n gbomo lowo ekuro’.

Orisiirisii owo lo wa. Owo tutu ati owo gbigbona. Owo ti a fi oogun oju eni ko jo ni a mo si
owo tutu. Owoo-gbona ni owo won fi ona eru ko jo. Ohun ni won tun n pen i owo eje, owo
okuta ati bee bee lo.

Okan-o-jokan ipede awon Yoruba fi pataki owo han. Won ni: ‘Owo ko si, eniyan ko suwon’,
‘owo ni ti oun ko ba si nile ki enikeni ma dabaa Kankan leyin oun.’ ‘Owo ni so omode di agba,
oun naa ni so agba di ewe.

Owo a maa fun eniyan ni iyi. Ojuse owo kan niyi. Awon Yoruba a maa fi owo ra iyi. Won ni ‘A
n wa owo lo, a pade iyi lona, ti a ba ri owo oun tan, iyi naa ni a o fi ra.

Owo ni a fi n pinle owo, ola ati ola. Opomulero ni owo je fun owo. Won ni “Owo la fi i peena
owo, bi egbaa ba so soke egbaa la a fi ja a sile.’ Ipede wonyi fi han pe owo se koko ninu owo-
sise. Won tile ni ‘Olowo lo lowo.’ Sugbon igbagbo w ape eni ti o ba n se eru nidii okowo, owo
bee ko ni mo on lowo. Won ni ‘eni to ba taja erupe yoo gbowo okuta’. Owo okuta tumo si
owo ti ki i duro lowo.
Oye owo ti a bar a oja n so bi a o se karamaasiki nnkan naa si. Bi a ko ba fi owo ra nnkan, a ki
i mo iyi iru nnkan bee. Eredi ti won fi ni ‘Oogun ta a ba fowo se. eyin aaro ni i gbe.’ ‘Bia bas i
fi owo ra ooyi, dandan ni ki o ko ni loju’. Oro agba niyi.

Bi owo se niyi to yii, awon Yoruba ni ‘Owo ni gbongbo ese.’ Gbongbo ni emi igi. Ti a ba si wa
ni ‘owo ni gbongbo ese, eyi tumo si wi pe owo n fa ihuwasi ti o lodi si ilana ofin yala ti ofin
Olorun, ti ijoba tabi ti awujo. Orisiirisii ona ni eda fi wa owo. Won n lu omolakeji ni jibiti, ti a
mo si ‘gbajue’, bee ni won fi eniyan soogun owo! Ese si ni gbogbo iwonyi lodo Olorun. Bee ni
“Elese kan ko ni lo laijiya” ni iwo Mimo so.

Ailowo lowo, won pe e ni ‘baba ijaya’. Okorin kan tile ko lorin, bee naa ni o tun so wipe owo
tun n sokunfa igberaga, bee ni ‘igberaga ni saaju iparun’. O ko o pe:

“Oro gbogbo lori owo


Yesi, otito ni
Aini owo baba ijaya
Yesi, otito ni
Alowo lowo, baba afojudi
Yesi, otito ni……..
Koseemani ni owo je. Ko si ohun tie da le se lai si ‘Kudi’?

Kirakita eda nitori aje ni. Owo, ohun ta a sonu, taa n wa kiri! Owo, apekanuko.

ALAYE: Aroko yii gun. Bi aoko ajemo-sispaya, a ri oniruuru oruko ti a n pe owo, oriki, iwulo,
anfaani ati alebu re. tun aroko yii ka, ki o sit un n ko niwonba.

AMUTILEWA
1. Ko igbese leta aigbagbefe mefa ti o mo sile leseese.

2. Ko aroko ajemo isipaya lori awon ori oro wonyi:

(i) Iku (ii) Iyan (iii) Ohunosin


AKORI EKO: ATUNYEWO EKO – ILE
Ni ile Yoruba, awon eko ti awon obi maa n ko omo lati kekere ni a n pe ni eko – ile. Yoruba ni
“Ile ni a ti n ko eso rode.” Awon eko bee ni ikini, imototo, isora, iwa to to si obi, agbalagba,
alejo, ati elegbe-eni. Omo ti won ko, to si gba, to si n mu eko naa lo nigba gbogbo ni a n pe
ni omoluabi. “Omo-Olu-iwa-bi”. Olu-iwa ni eni ti o je orisun gbogbo iwa rere aye. Bi enikeni
ba si je omo re, oluwa re ko ni sai ni ekun iwa rere; eni ti o ko gbogbo iwa rere po, ti gbogbo
elegbe ati olugba ka si ojulowo eniyan. Owe Yoruba ni “iwa rere ni eso eniyan”.

Abuda omoluabi po jantirere. Ara re ni owo, iteriba fun agba, osise, oninuure, onisuuru, eni
ti ko je huwa abosi tabi ireje si enikeji. Awon ona ti omode le gba huwa omoluabi niwonyi:

(i) Ibowo fun Agba: Awon obi a maa ko awon omo bi won se gbodo maa bowo fun
agba. Won ni “Omode to bam o owo we yoo ba agba jeun”. Eyi ni pe, omode to ba ni iwa
pele ati iwa rere yoo ma aba awon agba rin. Oniruuru iwa rere ni omode le hu si agba.

Ekini ninu won ni ibowo fun agba. Owe Yoruba ni “Aibowo fun agba ni ki i je ki aye gun.”
Omode ki i yaju si agba. Omokomo ti o ba daa an wo, iya ni iru won n je.

Ona keji ni pe, bi agbalagba ba n soro, omode ko gbodo pariwo tabi se ayonuso si oro ti agba
ba n so. Ni ile Yoruba, omode to gbeko ki i da si oro ti won ko pe e si. Bee ni omode ki i da
nnkan se laisi ase agbalagba nibe. Won a maa ko ni orin:

B’agbalagba ba n soro,
K’omode kekere a woye;
Kekere ko l’Erin fi ju Ekun lo
Oro gbogbo l’owe.”
Bakan naa, bi agba ba n sise ile, omode ko gbodo maa wo o niran. Ti omode ni lati bo si ibe
ki o pin ninu ise naa se ni ona ti yoo fi fuye fun agba. Bakan naa, bi agba ba ru eru nibi ti
omode wa, tabi n ru eru bo lati okeere, omode ni lati gba a lori re.

EKO ILE
Ni apeje, bi agbalagba ba pe leyin, ti ijokoo ko si fun un, eto omode ti o ba wa nibe ni lati
dide fun un lati jokoo si aare re. Bi o ba si je wi pe won jo de si asiko kan naa, agba ni lati ko
jokoo saaju omode. Ni oju agbo tabi ipade yoowu, bi won ba n pin nnkan, ti agba ni a o ko
yan.

Omode, ko gbodo pe agba loruko. A maa n fi oruko omo pe agba ti a ko le la oruko mo ni ori.
Bi apeere, ‘Iya Wale’, tabi ‘Baba Kudi’, tabi ki a kuku pe won ni baba, iya, tabi egbon eni. A ki
i lo ‘iwo’ fun agbalagba. “E” to fi owo han ni a n lo. “E kaaro”, “E kuuse o”, ati bee bee lo.
Okan pataki ni ikini je ninu asa ibowo fun agba.

Omode ko gbodo maa ki agbalagba ki o nawo si i lati bo won lowo, bee ni iwa afojudi ni ki a
ma aba agbalagba soro pelu pako ni enu laaro.
“Iwa rere ni eso eniyan”. Omode ti o ba huwa rere si agba yoo ri oore gba, ojo re yoo si pe ni
aye. Awon omode to n bo leyin re yoo si bowo fun un, nitori “Aseele ni abo-aba.”

(ii) Kiki eniyan bi o se ye ni gbogbo igba: Kekere ni awon obi ti n ko omo ni


orisirisi ikini. Bi omodekunrin ba ji laaaro, eto ni ki o ki awon obi re ninu ile towo-towo. “E
kaaaro o, Momo” tabi “Ejiire Momo mi”. Omode ni lati fi ara re han bi omo ti o gbekoo nipa
didobale bi o ba je okunrin tabi kikunle, bi o ba je obinrin. Omode ki i duro gbagidi ki
agbalagba. Abiiko ni won n pe iru omo to ba huwa omugo bee. Aaro nikan ko ni a n ki ni.
Omode gbodo mo bi a se n ki eniyan ni osan, irole, ale ati nigba gbogbo. Bi omode ba n ki
agbalagba, yoo lo oro eni pupo fun eyo agba kan soso: ‘Mo n ki yin ni o!’ ‘Mo ba won nile’,
‘Eyin ni mo n ki, sa! Ati bee bee lo.

“E kuule” n la a ki araale, ‘E ku ona’. n la a ki ero ona. ‘Omo olokun, abaja-lorun, maa wo ‘le’
o!’ n la a ki omolooku, bee ni ‘iyawo a bi ako a bi abo o’ tabi ‘eyin iyawo ko ni mo eni o’, ni a
n ki eni to sese se igbeyawo osingin. Gbogbo ikini wonyi ni omo Yoruba gbodo mo lati ewe.
Eyi le le die fun omode, sugbon ‘Tita riro la a kola, bi o ba jina tan, oge ni i da’. Mimo eniyan
an ki ni akoko to ye ati ona to to n iyi fun ni.

(iii) Ninu iwa Rere ati Suure: Gege bi itan isenbaye, bi awon Yoruba se gba ORI gbo
naa ni won gba IWA gbo. Won gba pe bi eniyan yan ori rere, bi ko ban i iwa rere, aye ati
orun re ko le dara.

Iwa ti a n wi yii, obinrin ni ati wi pe aya Orunmila ni. Orunmila ko iyawo re Iwa sile nitori o ni
obun pupo, Iwa si ko lo si ile Olodumare. Se omo Olodumare ni Iwa nitori pe oun ni i se
akobii Suuru, to je aremo Olodumare. Nitori eyi ni a fi maa n so pe “Suuru ni baba iwa”. Igba
ti Orunmila ko iwa sile tan, ni aye re ko ba dara mo. Ko ri se mo, ko ri je, ko ri mu, bee ni
gbogbo eeyan lo n ri i ho. Nigba ti aye Orunmila waa dorikodo nitori pe iwa nu-un, lo ba
mura lati wa obinrin re lo. Nitori “Bi iwa ba nu eeyan, aye re lo nu un….” Bayii ni Orunmila se
bo sinu eku Eegun, o bere si i wa Obinrin re kaakiri. O wa a de’le Alara, eji osa, omo amurin
kan dogbon agogo. O wa a de’le Ajero, omo ogboju koro ija jale. O wa a de’le Owarangun
aga, amota ede, oniguru, agun f’owo laba owo teteete. O wa de gbogbo ilea won oloja
mereerindinlogun, sugbon ko ri i. L’o bag bona orun lo. Nibe l’o ti war i Iwa. O bere si i be e
pe ki o ba oun kalo si ile, sugbon Iwa ni oun ko lo. O wa ki Orunmila ni ilo pe ki o maa fi owo
re tun iwa ara re se laye. Lati ojo naa l’o ti di wi pe owo onikuluku l’o fi tun iwa ara re se. eyi
ko ni wi pe iwa ati suuru se pataki. Ara abuda eko ile ni.

Yoruba n ko omo pe bi a se n toju obinrin eni ni a se n toju iwa eni. Bi eeyan ba w alai ni iwa,
egbe ati otubante ni. Won ni:

B’a a lowo
B’aa niwa
Owo olowo ni
Iwa, iwa l’a n wa o,
Iwa……
Ara awon iwa rere ti omo n ko ni ki a ma so otito, ki a si maa ni suuru. O ni:

Ibinu ko da nnkan kan fun ni


Suuru baba iwa
Agba t’o ni suuru
Ohun gbogbo l’o ko ja….”
Omode ki i wo agba loju, bee ni won ko gbodo su agba lohun bi won ba n ba won wi. Igbesi
aye re gbodo maa je apeere suuru ati irele okan, ti yoo je awokose fun awon eniyan.

(iv) Ninu Iforiti: Iforiti se koko ni aye eda. Bi isoro ba de, a gbodo ko omode bi won se n
fi ori ti i, ti won ko fi ni bohun tabi kaaare. Yoruba ni “Iforitu lo ni ohun gbogbo”. Iforiti ni a fi
n segun isoro yoowu ti i baa doju ko ni. Pelu iforiti, omo yoo le se ohun ti won ro wi pe o
koja ogbon ori re.

(v) Otito ati Oro Rere Siso: Otito siso je okan gboogi ninu ohun ti obi n ko omo lati
kekere. Won ni ki a soro ki a baa bee ni iyi omo eniyan. Lati pinnisin ni a ti n ko omo pe iro
pipa ko dara. “Oro rere ni n yo obi ni apo, oro buburu ni yo ofa l’apo.” Omo ni lati maa ni
ohun rere lenu nitori oro enu eniyan lo n fi bi okan ati inu eni ti ri han. Omode ki i soro
buburu lenu. Kaka bee o dara ki o maa woye. Omode gbodo mo igba to ye ki o soro ati igba
ti o ye ki o dake. Gbogbo awon eko wonyi ni won sodo sinu eko ile.

(vi) Igboran: Igboran se pataki fun omode. Omode n ko bi a se n gboran si obi ati ebi
lenu. Igboran ki i je ki omode sise. Awon agba ni “Aguntan ti o b aba ajar in dandan ni ki o je
igbe”. Bee ni “A ki i pe ni lole ki a maa gbe omo ewure sere”. Imoran ni awon owe wonyi lati
enu awon agba. Owe je ara ona ti awon Yoruba fi n ko omo ni eko ile. Omo ti o ba mu
imoran agbo lo ni a n pe ni ologbon omo. “Omo ti a n ba wi to warunki, yoo parun ni ogan.”
Oro agba ni.

(vii) Oninu-didun Olore: Bi omoluabi ni ohunkohun, inu re a maa dun lati fun
elomiran ninu re. ohun to dara ni ki a maa se itore fun awon alaini ati arugbo.

Bi a se n ba eniyan gbe po ni irepo

i. Ifarada: A ni lati ni ifarada ki a to le gbe ni irepo pelu awon eniyan ni awujo. A


gbodo year fun ohun to je mo ikanra ati iwa igberaga.
ii. Imowa fun oniwa: Bi a ba n ba eniyan gbe po, a ni lati mo wi pe iwa wa ko le
sokan. Tayewo ati Keyinde, ti won gbe inu kan naa fun osu mesan-an ko mu iwa
kan naa waye. Lati wa ni irepo, a ni lati mo iwa fun oniwa.
iii. Suuru nini ni akoko wahala: A ko gbodo je ki wahala tan wan i suuru. ‘Suuru lere’
ni awon agba wi. Ti a ba le ni suuru, ipepo wa ni awujo ko ni soro.
iv. Yiyan ore to daralati ba rin: “Fi ore re han mi, ki n so iru eeyan ti o je. Ni awujo, a
gbodo mo iru eni ti a o ba kegbe. Won ni “Agubtan to ba aja rin, a je igbe.” Egbe
rere lo pe. Iru won ko ni si wahala, bee ni a o maa wan i irepo ninu ile ati ni ode.
v. Ife: Won ni “Ife ni akoja ofin”. Ki a feran omolakeji ni ofin ti Olorun fun wa ni. Ti
ife ba wa ninu ile, ikoriira, aso tenbelekun yoo di ohun afin-seyin ti eegun n fi aso.
vi. Ninu iberu Olorun: “Iberu Olorun ni ipinlese ogbon”. Bi a ba sun mo Olorun, ti a
n ka oro re, ti oro re si n gbe inu eni, gbede bi o se n ro koko lehinkunle ni ibagbe
wa pelu awon eniyan yoo ri. Bi a ba wa ninu Oluwa, ti Oluwa si n gbe inu wa, ko
sewu loko, afi giiri aparo.

Awon ona bi a se n year fun iwa aito ni awujo

(i) Nipa titele imoran awon obi eni


(ii) Mimo iru ore ti a oo bar in tabi lilodi si egbe buburu: aguntan to b aba ajar in yoo
je igbe.
(iii) Ki a maa tele ofin Orile-ede
(iv) Nipa fifun ara eni ni ijanu nipa oro siso
(v) Nipa rerun ni ona to to nigbogbo igba
(vi) Nipa titele ofin Olorun ti a gbo ninu iwaasu ati titeti si oro Olorun
(vii) Rinrin ni awujo awon olododo.

Ise Amutilewa

1. So ona marun-un ti a le gba huwa omoluabi

2. So ona marun-un ti a fi le year fun iwa aito lawujo


OSE KEJI

AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA

Ninu oro ‘baba’ ege meji ni a ni: ‘ba-ba’. Ege kookan ni o ni iro faweli ati ami ohun. Ege
kookan yii ni a n pe ni silebu.

ABUDA SILEBU

(i) Silebu le je iro faweli kan tabi iro konsonanti ati faweli. Apeere:

i – ya
ba – ba
ko – bo
e – gbon
(ii) Iye ibi ti ohun ba ti je yo ninu oro kan ni yoo fi iye silebu ti oro naa ni han. Bi apeere:

Ife – Ibi meji ni ohun ti je yo (Silebu meji)


Omuti – Ibi meta ni ohun ti je yo (Silebu meta)
Ikadii – Ibi merin ni ohun ti je yo (Silebu merin)
IHUN SILEBU

Apa meji ni silebu pin si. Awon ni:

(i) Odo silebu


(ii) Apaala silebu

(i) Odo Silebu: Odo silebu ni ipin ti a maa n gbo ketekete ti a ba pe ege silebu kan. Ori re
ni ami ohun n wa. Iro faweli tabi konsonanti aranmu asesilebu ‘n’ ni won le je odo silebu.
Odo silebu ni a fala si nidii wonyi:

i-wa
i-gba-la
o-ro-n-bo
(ii) Apaala Silebu: Awon iro ti a ki i gbo ketekete ti a ba pe oro sita. Konsonanti inu silebu ni o
maa n duro bii apaala silebu. Apaala silebu ni a fala si nidii wonyi:

i-wa
o-san
du-n-du
EYA IHUN SILEBU

(i) Silebu Onifaweli Kan (F): Eyi le je eyo faweli kan soso. Apeere iro faweli bee ni a fala
si nidii wonyi:

A ti lo
Mo ri o
Mo ka a
Gbogbo iro faweli wonyi le da duro bii silebu:

a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
(ii) Silebu Alahunpo Konsonanti ati Faweli (KF). Apeere iru silebu bee ni wonyi:

wa, ba, bϙ, bҿ, ri, ra, mo, kϙ


gbϙn, ran, tan, rin, kun, wϙn
(iii) Konsonanti aranmupe asesilebu (N). Apeere iru silebu bee niyi:

n lϙ
o-ro-n-bo
i-sa-n-sa
PINPIN ORO SI SILEBU

Awon oro kan wa ti won ni ju silebu kan lo ninu ihun. Awon oro bee ni a pe ni ‘oro olopo
silebu’. Apeere:

(i) Oro Onisilebu Meji

Oro Ipin Ihun Iye silebu


ҿgbon Ҿ-gbon f-kf meji
ifҿ i-fҿ f-kf meji
iku i-ku f-kf meji
Bϙla Bϙ-la kf-kf meji

(ii) Oro Onisilebu Meta

Oro Ipin Ihun Iye silebu


Idoti I-do-ti f-kf-kf meta
Agbado a-gba-do f-kf-kf meta
Ijangbon i-jan=gbon f-kf-kf meta
Kansu ka-n-su kf-n-kf meta
Gbangba gba-n-gba kf-n-kf meta
Banjo Ba-n-jo kf-n-kf meta
Gende Ge-n-de kf-n-kf meta
Gbolahan Gbo-la-han kf-kf-kf meta

(iii) Oro Onisilebu Merin:

Oro Ipin Ihun Iye silebu


Ekunrere e-kun-re-re f-kf-kf-kf merin
Alangba a-la-n-gba f-kf-kf-kf merin
Opolopo o-po-lo-po f-kf-kf-kf merin
Olatunji O-la-tun-ji f-kf-kf-kf merin
Mofiimu Mo-fi-i-mu kf-kf-f-kf merin
Ankoo a-n-ko-o f-n-kf-f merin
Laaro la-a-a-ro kf-f-f-kf merin

(iv) Oro Onisilebu Marun-un

Oro Ipin Ihun Iye silebu


Alaafia a-la-a-fi-a f-kf-f-kf-f marun-un
Ogunmodede o-gun-mo-de-de f-kf-kf-kf-kf marun-un
Ogedengbe o-ge-de-n-gbe f-kf-kf-kf-n-kf marun-un
Alagbalugbu a-la-gba-lu-gbu f-kf-kf-kf-kf marun-un
Agbalajobi a-gba-la-jo-bi f-kf-kf-kf-kf marun-un
Nigbakuugba ni-gba-ku-u-gba kf-kf-kf-f-kf marun-un

(v) Oro Onisilebu Mefa

Oro Ipin Ihun Iye silebu


Gbangbayikita Gba-n-gba-yi-ki-ta kf-n-kf-kf-kf-kf mefa
Orogodoganyin o-ro-go-do-gan-yin f-kf-kf-kf-kf-kf mefa
Afarajoruko a-fa-ra-jo-ru-ko f-kf-kf-kf-kf-kf mefa
Alapandede a-la-pa-n-de-de a-kf-kf-n-kf-kf mefa
Konsonanti ko-n-so-na-n-ti kf-n-kf-kf-f-kf mefa
Bookubooku bo-o-ku-bo-o-ku kf-f-kf-kf-f-kf mefa

ISE AMUTILEWA

1. (a) Ki ni Silebu? (b) So abuda silebu meji ti o mo pelu apeere

2. Ko apeere oro marun-un ti o ni konsonanti aranmupe asesilebu. Pin won si iye silebu.

3. Pin awon oro wonyi si iye silebu won:

(i) Akalamagbo (ii) Olododo (iii) Aworerin-in (iv) Akikanju

(v) Osoosu (vi) egbeegberun (vii) ileladewa (viii) igbaradi

(ix) iyaloosa (x) Akerefinusogbon


AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI

Ise ni oogun ise


Eni ise n se ko ma b’Osun
Oran ko kan t’Osun
I baa b’Orisa
O di’jo to ba sise aje ko to jeun
“Owuro lojo, ise la a fi i se ni Otuu’Fe”. Kaakiri ile Yoruba, ise ni won n fi owuro se. won
gbagbo wi pe ‘Ise loogun ise’. Eredi ti won fi mu ise abinibi won ni okunkundun. Se ‘eni mu
ise je, ko sai ni mu ise je’. Iran Yoruba lodi si imele, won gbagbo wi pe ‘owo eni ki i tan ni je’.
Bi onikaluku ba ti ji idi ise ni won n gba a lo nitori ‘idi ise eni ni aa ti mo ni lole.’ Ibi ti baba bat
i n sise ni omo yoo ti maa wo owo re, ti yoo si tibe maa ko o. won ni “Atomode de ibi oro n
wo finnifinni, atagba de ibi oro n wo ranran.’ Owe yii fi han wa pe ko si ohun ti a fi omode ko
ti a si dagba sinu re ti a ko ni le se daadaa. Eyi ni ise abinibi.

PATAKI ISE ABINIBI

(i) Oje ise to se fi le omo lowo bi ise asela tabi ona ola
(ii) O n dana airise se laaarin ebi. Ko fi aaye sile fun arinkiri awon ewe. Yoruba ni:
“Owo to ba si dile, ni esu n ya lo”.
(iii) Ko si pe a n dajo akoko ti omo yoo lo lenu ekose. Lati kekere ni yoo ti bere; ko si
to ya ise lodoo baba re, yoo ti di okunrin, okan re yoo si ti bale si ise naa ni sise.
Opolopo ise to ba n se, baba re ni yoo maa se sin titi ti baba re yoo fi ya ise fun-
un. Ninu iwe wa kin-in-ni, a pin ise abinibi si isori merin wonyi:

Ise Agbe, ise ode, ise ona ati ise owo. Awon ise abinibi ile Yoruba ti a o yewo siwaju sin i: Ise
Agbe, Ise Ajorin, Ise Alapata, Ise Onisowo, Ise Akope ati Ise Gbenagbena.

1. ISE AGBE
Ise agbe ni ise ti o gbajumo julo ninu ise ti won n se ni ile Yoruba. Awon agbe ni won n
sogbon ounje, ti won n pese ounje fun awa eniyan. Ounje ti a n je ni o n fun ara wan i okun
ati agbara lati sise oojo. “Ona ofun, ona orun”. Bee ni ‘bi ebi bat i kuro ninu ise, ise buse’.

PATAKI ATI IWULO ISE AGBE

(i) Ipese Ounje


(ii) Ipese ohun elo fun awon ile-ise
(iii) Ipese ohun amusoro aje
(iv) Ipese ise

Agbe pin si orisii meji wonyii:

(i) Agbe Alaroje: Iwonba oko ti won yoo fi bo enu ebi ni agbe alaroje n da. Won n gbin
agbado, ege, ogede, ata ati ewedu. Eyi ti won ba je ku ni won n ta ni oja fun ara ilu.
(ii) Agbe Alada-Nla/Oloko-Nla: Awon agbe wonyii ni awon ti n fi ise agbe sise se, ti won n da
oko nla, ti won si n kore repete. Bi won se n ta ni oja adugbo, ni won n ko won on koja si ilu
miiran. Awon agbe yii maa n gba opolopo osise onise odun. Won le ra eru tabi ki won ya
iwofa.

ORISII ILE TI AGBE N DA

(i) Ile Igbo: Ile igbo/egan dara fun ogbin igi owo bii koko, obi, orogbo, ope, osan,
kofi, roba, agbon.
(ii) Ile Odan: Ile odan tabi papa dara fun ogbin agbado, isu, ege, egunsi, eree, okaa-
baba, owu, epa, anamo ati eso bii mangooro, opeyinbo ati bee bee lo.
(iii) Ile Akuro: Ile akuro dara fun ogbin agbado, ila, ata, efo lorisirisi, ireke, ati awon
eso bii oronbp, mangooro ati bee bee lo.

ORISII OKO

Orisii oko meji to wa ni:

(i) Oko Egan: Oko egan ni oko titun ti enikan ko ti i da ri. Igbo kijikiji ni. O maa n jinna si ile.
Won maa n ni ahere ti won le seun tabi maa gbe, ti won yoo si maa wale ni osoosu, tabi
leekan lodun. Awon ni a n pen i ‘Ara-oko’ tabi ‘Agbe-Arokobodunde’.

(ii) Oko Etile: Oko etile ki fi bee jinna si ile. Awon ti n da oko etile ki saaba sun ni oko. Bi won
ba lo ni aaro, won le pada si ile ni ale. Opo igba ni oorun tanmode-soko maa n mu won on di
orun si oko.

OHUN ELO ISE AGBE: Oko, Ada, Akoko, Aake, Idoje ati Obe

Awon isoro to n doju koi se agbe

a. Airi ohun-elo idako igbalode lo: Ada, oko ni won si n lo. Won ko ni anfaani lilo ero
katakata iroko, ikobe, oogun ifinko, ipako ati bee bee lo.
b. Ayipada Oju Ojo: Oda ojo ni akoko ti ko ye tabi ojo arooda maa n se akoba fun ikore
agbe;
c. Awon Eranko: Awon eye, kokoro ati awon eranko bii oya maa n ko lu oko, ti won si le
mu ki oko, ti won si le mu ki oko maa se daadaa.

Agbe ni Ode-Oni: Ni ode-oni, tabi-tijoye, tokunrin-tobinrin ni won n sise agbe nitori irorun to
de ba ise naa.

Awon ero katakata, ero-irole, tabi ikobe wa kaakiri ti won le ya ni owo pooku. Bee ni oogun
igbalode buu ajile, korikori, taritari wa fun awon agbe onikoko.

Awon onimo ijinle, egbe alajosepo, ile ifowopamo ati egbe alajaseku wa ti won n ran awon
agbe ni owo fun itesiwaju ise won.
2. ISE AJORIN
Ise ajorin ni awon ti won n sise irin jijo, ti a mo si ‘Weda’ ni ode-oni. Bi a pe won ni alagbede,
a ko jayo pa nitori igbe kan naa ni ode won n de. Ise yii lowo lori pupo.

IWULO ISE AJORIN

(i) Bi ko si ajorin, awon agbe ko le sise. Awon ni won n jo ada, akoro, aake tabi obe
to ba kan, tabi oko ti o bay a.
(ii) Ni ode-oni, awon ajorin igbalode ni won n jo irin geeti ati ferese ile.
(iii) Awon naa ni won n jo awon ibi ti o ba je ni ara oko oju omi, oju-irin ati ti ori-ile,
tatapupu, omolanke ati bee bee lo.

OHUN ELO WON: Ni aye atijo irinse alagbede ko ju owu, omo owu, iponrin, ewiri, emu ati
eesan lo. Awon ajorin ode-oni n lo ina gaasi ati kanbaadi, irin ati bee bee lo.

ILANA IKOSI: Niwo igba to je ise abinibi, kekere ni omo won yoo ti maa fi oju si ise yii. Igba ti
o ba dagba ni yoo to da ise ya.

3. ISE ALAPATA
Ise alapata je ise abinibi awon iran kan ni ile Yoruba. Awon okunrin ni won po nidii ise yii, bi
o tile je pea won obinrin naa ko gbeyin ninu owo eran tita. Ise alapata je mo ise eran pipa,
eran tita. Maluu pipa ni a mo won mo teleteleeri. Sugbon ni ode-oni won ti n pa ewure ati
agbo ta. Won tile ti n ni awon odo-eran ti won ti n pa awon eran wonyi.

PATAKI ISE ALAPATA

(i) Nipase awon alapata ni eran se n wo ile Yoruba lati oke oya ni opo yanturu. Awon
ni won n seto bi won se n ko Maluu, Agbo ati Ewure wole.
(ii) Eni to mo oju ogun ni pa obi ni ‘Re’. Awon alapata ni won mo ogbon mimu awon
eran wonyi ti won ba ja ni oriso, bi a se n pa won ati kikun won.
(iii) Ise kekere ko ni eran-jije n se ni ago ara. O n fun ara wa lokun, mu ki ounje wu ni
je.

AWON OHUN ELO ALAPATA

(i) Obe: Obe to mu sarasara ni won fi n pa eran yoowu ti won ba fe pa. obe naa ni
won fi n kun un si iwon esipon ti a fe.
(ii) Ada: Ibi to le ni ara eran ni won n fi ad age. Bi apeere, ese eran, ori ati beebee lo
(iii) Aake: Ise kan naa ni alapata n fi aake ati ada se. aake wulo lati fi sa egungun ti
ada ko ran tabi to le ba enu ada je. Won le fi aake fo ori Maluu, ese tabi eyin re.
ILANA IKOSE: Awon omo alapata maa n koi se yii lati kekere. Bi omo bas i se n dagbe si ni
yoo maa mo apadelude ise siwaju sii. Ise yii yoo gba omode ni odun marun-un si mefa ki o to
le gba ominira.

4. ISE ONISOWO (OWO-SISE)


Okan ninu awon ise abinibi aye atijo ni owo-sise. Awon iran Ijesa ni a ko mob ii onisowo aso.
Awon ni a n pen i ‘Osomaalo’ ni aye atijo. Awon onisowo ni won n ra, ti won si n ta oja fun
awon eniyan. Awon obinrin ni won po ju lo nidii ise-owo.

Ise owo pin si orisiirisii. Alajapa ni a n pe awon ti won n ra tabi ya nnkan oko bii koko, ogede,
isu, elubo, gaari, osan ati bee bee lo. Awon miiran n sowo ate. A n pe won ni ‘alate’. Awon
miiran si wa ti won je onisowo aladaa-nla, ti won n ta aso-ofi, bata ati bee bee lo. Bee ni
eran-osin bii ewure, agbo, maluu, eja, bee ni awon miiran n sowo re. ise owo ni owo lori
pupo.

PATAKI ISE ONISOWO

(i) Won n je ki oja da arowoto awon onraja ni asiko


(ii) O n pese ise asela fun ontaja
(iii) Ko mu pakanleke lowo, bi eniyan ba se karamasiki oja to ni a yoo se ta si.

OHUN ELO ISOWO

a. Owo-idokowo: Owo ni a fi n pinle owo. “Bi owo bas i ti mo ni oogun un mo”. Bi owo
ti a fi bere wow ba se po to nioja eni yoo se tobi si.
b. Ibi Isowo: Ibi ti a o ti maa se owo se pataki. O le je inu oja, iwaju ile eni tabi ni irona.
Ibe gbodo je ojutaye, ti oja wa yoo ti ta.
c. Ipolowo Oja: ‘Ipolowo oja ni agunmu owo’. Awon onisowo maa n kiri tabi pate oja
won ki a le mo ohun ti won n ta, ki aje le bu igba je.

ONA IKOSE: Omo le koi se-owo ni owo obi bi ise abinibi tabi ki o lo ko o bi awose. Won ni ‘Bi
a se n kose ni a ko iyara’. Ijafara se pataki nidii ekose owo.

5. ISE AKOPE
Ise ohunrin ni ise akope. Okan ninu awon ise ti a ba lowo awon baba-nla wa ni. Tokunrin-
tobinrin ni won mo riri ise yii. Awon ni won n ko eyin ope ti a fi n se epo-pupa. Ise elege ni.

Ise yii gba suuru ati aya nini. Eniyan to ban i ooyi oju ko le sise akope. Igba miiran wa ti owo
palaba akope le segi, ki igba ja, tabi ki ese ye ni ara igi ope tabi ki ejo nla san won ni ori ope.
Gbogbo nnkan wonyi lo le fa ki akope jao. Koko bii irin sin i idi igi ope maa n le. Idi niyi ti o fi
je wi pe opo eni ti o ba ja lati ori igi ope ki i fi i ye. Eegun eyin tabi ti ibadii le kan, tabi run
yegeyege. Idi igi ope naa ni won n sin oku bee si.
PATAKI ISE AKOPE

(i) Ipese epo isebe: Epo ni iroju obe. Bi ko si akope, obe efun ni a ba maa je.
(ii) Ipese Owo ati Apere: Imo ti akope ge lule lati ori igi open i a fi n fa owo ti a tun n
fi ifon re hun apere. Bi owo ko si bi akitan ni ilr ati ayika i ba da. Bi agbon ko bas i
ni ahere, owo ni a ba fi ko isu wale.

AWON OHUN ELO AKOPE

a. Igba: Igba ni okun agba ti won lo pot i akope fi n gun igi ope. Igba yii maa n gbopon,
bee ni a maar o.
b. Aake: Aake ni akope n fi i re imo danu, ki o le ri aaye geo di eyin lule.
c. Ada: Akope le fi ad age imo ori ope, bakan naa ni o le fi sa odi eyin lule.s

EKOSE: Bi o tile je omode le maa fi oju si bi won se n gun ope, o gbodo di gende ki o le da ko
ope. O le bere lati ori opekete. Eyi ni ope kekere ti owo lee to eyin ori re ni ile. Won ni
“Opekete n dagbe, inu adamo n baje”.

6. ISE GBENAGBENA
Ise gbenagbena je okan pataki ninu ise ti a ba lowo awon baba-nla wa. Awon okunrin ni won
n sise yii. Ise yii je ise ti toba-tijoye n karamasiki re. awon ni won n gbe igi opo-ile, ilekun,
apoti ijokoo Oba. Won le fi igi gbe Ekun, Ologbo, Odidere, Erin ati orisirisii ere, apeere
awonti a n ba pade ni aafin Oba tabi ilea won olola ati awon ijoye. Awon ni won n gbe opon-
ayo, opon-ijeun, orisii ere fun ilo awon ara ilu ati awon ti a n ri ni iyara ikohun-isebaye-si bi
eyi ti o wa ni Ile-Ife ati Binni. Gbenagbena naa ni won n se eeku ada, igi oko, igi aake ati bee
bee lo fun ilo awon agbe. Owo tabuu ni won n pa.

PATAKI ISE GBENAGBENA

(i) Ko je ki asa wa lo si okun igbagbe


(ii) O je ona ipawo wole si apo gbenegbena
(iii) O je ona ipawo wole fun Ijoba, ti wo ba fi awon ere wonyii sowo si oke okun
(iv) O pese ise fun awon odo

AWON OHUN ELO WON:

a. Aake: Aake ni gbenagbena fi n ge igi ti won fi n gbe ere lule, ti won yoo sig e si
orisiirisi ike
b. Ada: Ada ni a n lo dipo aake lati ge igi ti a fe lo si ike-ike. Ohun naa ni a fi n bere ere
gbigbe
c. Obe: Ti ise ba de ibi elege bii ki a fe se oju, imu, eti, enu, oyan-aya, obe ni a n lo. Oun
ni won fi n gbe ara nnkan, ki o le dan daadaa. Bi won se ni obe nla ni wo ni kekere ti
won fi n dan ara ere tabi opa itile.
d. Osese: Oseseni a fi n da iho sinu igi ti a fe fi gbe ere tabi ara nnkan miiran ti a fe gbe
Orisii Igi ti won n lo

i. Igi Iroko tabi Oganwo: Igi wonyi le pupo. Awon ni a fi n gbe odo, opa itile.
ii. Igi Awun: Igi yii ko le koko bii igi iroko tabi oganwo. Oun ni a fi n gbe ere, opon-
ayo.

ILANA IKOSE: Awon ti won ba je omo gbenagbena le bere lati kekere. Won yoo si lo to odun
mewaa ki won to mo ise naa dunju. Awon ti won wa ko ise yii bi awose yoo lo bii odun
marun-un si mefa ki o to gba ominira.

Ni ile Yoruba, ni ojo igbominira, ti o ba je ise awose, oga yoo fi oti ibile tabi oyinbo gba adura
fun omo ekose. Awon obi omo-ekose naa yoo gbe ohun jije-mimu kale lati je ki won mu.

ISE AMUTILEWA

1. So pataki ise isenbaye


2. So iwulo ise abinibi meta
3. So orisii ise abinibi meta ki o si daruko ohun elo ise won
4. So pataki ise agbe marun-un
OSE KETA

AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI

Aroko ti a ko to da lori itakuroso laaarin eniyan meji tabi ju bee lo ni a n pen i aroko oni-
soro-n-gbesi.

Abuda Aroko Onisoro-n-gbesi

(i) O maa n ni akopa bii ere ori itage


(ii) Oro enu akopa kookan maa n han ni iwaju oruko won
(iii) Iso bee ko gbodo gun ju, ko si se regi
(iv) Oro erin ati awada kii gbeyin, a si gbodo year fun awada ako
(v) Isesi won ni a maa n fi sinu ami akamo olofo ( ).

E je ki a ka aroko oni-soro-n-gbesi yii wo, bi apeere:

(Won sese gbe oga titun kan de si ile-iwe re, ko iforo-jomi-tooro oro to waye laarin
akekoo meji lori oga titun yii sile).

OGA TITUN

(Ranti ati Yemisi wa ni Kilaasi S.S.2. Won pade ni ikorita meta ni eba ile ounje. Yemisi fe lo
kawe, Ranti fe lo pon omi)
Ranti: (o sunmo Yemisi) E ma si ku amojuba t’Oga titun
Yemisi: Baa se ki ni naa nu un. N o kuku tii ri won soju
Ranti: Ma je k’aye o gbo. Iya to wa si ipade apejopo akekooati oluko ni aaro ana
Yemisi: (o mo’ju tai) Se won ni mow a n’be ni? Mo pe de. Kilaasi ni mo gba lo taara
Ranti: Eyin isa-n-sa. Oju yin re e. ipade ohun ma larinrin
Yemisi: Ki lo sele? Won fun yin lo’oyin la? Gbee si mi leti, joo
Ranti: Oyin ko, ado ni. Won kan fi oga han wa ni. Oun alara si gba wan i iyanju pe ki
a tepa mose.
Yemisi: Eyuun lo wa mu ipade dun? Osise ni wan i?
Ranti: Ki lo fe ki iya-oniyaa so? Oro iyanju ni akekoo n fe. Abi lo fe ko so. O kuku ti
se’pade pelu awon oluko ati awon pirifeeti.
Yemisi: (O tewo pe e) Igba wow a ni ‘pade tiwa? Abi?
Ranti: Ipade wo ni o fe ki Alaaja tun ba wa se?
Yemisi: Wa na, se Musulumi ni?
Ranti: Musulumi ponbele ma ni. O kirun ju awo lo. Oro po. Iya naa le soro lataaro
dale!
Yemisi: Awon akekoo Musulumi bo saye nu un. Logan ni yoo ko Mosalasi ti won ti ko
pati lati bi odun merin.
Ranti: O ma ni oun ko boroesin wa. O ni bi esi idanwo asejade wa yoo se gbe peeli
soke sii ni o je oun logun.
Yemisi: Too. Olorun a fun un se. Awon alale a tii leyin
Ranti: Ti awon alale ti se wa je ninu oro ile iwe?
Yemisi: Ki lo fe n so? Se bi, won ni ‘Isese lagba’?
Ranti: Ooto ma kuku ni. Obatala a ba a f’ase sii
Yemisi: Ase o
(won pinya)
ALAYE
Iwontunwonsi afo enikookan se regi. Ede won lo taara, bee ni awada ibe mo niwon. Akekoo
meji pere ni a lo. Ko dara ki akopa po repete.

ISE AMUTILEWA

1. Ko abuda aroko oni-soro-n-gbesi marun-un ti o mo


2. Ro o lokan ara re pe iwo (Femi) ati ore re (Bayo) lo woran are Boolu afesegba to
waye laarin Super Eagles ati iko agbaboolu Argentina. Super Eagles feyin won bale ni
amin ayo merin si ookan. Eyin mejeeji wa n foro jomi-tooro or obo wa si ile. Bi oro
naa se lo re e:

AARE BOOLU

Femi: Boolu ale yii ko yoyo, o dun yato. Abi?

Bayo: Bee ni. Mo gbadun re gan an ni. Ki lo ri si ayo ti Kola gba wole ti Refiri fagi le
un?

Femi: Mo rii. O dun mi wonu eegun. O dabi eni pe Refiri ti fon fere ki Kola to gba
boolu naa s’awon.

Pari iforowero yii. Lo awon gbolohun ibeere ati ede iepri to je mo are boolu afesegba.
AKORI EKO: ONA IBANISORO
Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye
won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti
won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.

Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa
loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro
lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran
paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.

Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba.
Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.

A. ONA IBANISORO NI AYE ATIJO

1. Lilo Eya Ara fun Ibanisoro: Eya ara ti a n lo fun Ibanisoro je awon eya ara ti a le gbe soke-
sodo, ti eni ti a n fii ba soro le ri. Eni bee le wan i egbe eni tabi wa nibi ti ko jinna. Apeere
awon eya ara naa niwonyi:

(i) Oju: Oju se pataki ninu eya ara ifo. Bi apeere, a le fi oju fa ‘ni mora’, kilo fun eniyan bee ni
a le fi na eniyan lailo pasan. Eni ti o ba kuna lati mo eyi ni won n bun i alaimojumora. Bi
apeere,

AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba n soro, ti a wa se oju si eni naa Ki o joo, gbe si mi leyin
Ki o dake, pe enikan n bo
Ti a bam o eniyan loju N ko gba tire. Ami ija ni eyi
N ko fara mo oro ti o n so
Fe oju mo omode A fi n deru ba a ni
Ti a ba fi odo oju tabi oju isale wo eniyan Ami ife ni. Okunrin le fi oju isale wo obinrin.

(ii) Ori: Ipa pataki ni ori n ko bii ona Ibanisoro. Igba miiran, eniyan le so ori ko, won a ni
oluware n ronu. Bi o ba n fi owo ja ori, to n fi ese jale, ajalu laabi kan ni o sele sii. Bi apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Ti awon eniyan bag be ori so si nnkan ti a n O dara. Maa se lo
se
Ti won ba gbon ori Ami ikaaanu ni naa tabi ilodi si nnkan to n
se.
Ori gbigbon Rara o. lati fi ilodi si han
Ti won ba bi wa leere oro, ti a mi ori Tooto ni. Bee ni, tabi bee ko
Ti a ba mi ori si isale A pe eniyan pe ki o wa
Ori mimi sotun-un, sosi Rara o tabi bee ko
(iii) Imu: Yoruba kii dede yin imu ti ko bas i ija tabi ikunsinu. Bi apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba yinmu si eniyan A n fi eni naa sefe ni, wi pe a ko ka oro ti eni
naa n so si rara

(iv) Enu: A le lo enu lai ya a tabi sii raa. Bi apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba yo suti tabi yege enu si eniyan A n fi eni naa se yeye ni tabi pe oro eni naa
ko mu ogbon wa
A le fi enu sufee Ko si oro ti a ko le fi so

(v) Ejika:

AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba n ban ii soro ti a gbun tabi so ejika Mo gba oro naa wole bii otito
Mo lodi si oro naa

(vi) Ese:

AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba fi ese janle Ami ilodi si nnkan kan ni eyi je
Tite eniyan lese mole A n kilo fun un pe ki o ma se nnkan kan tabi
ki o dake
A le fi pe akiyesi re si nnkan kan
Fi ese mole A fi n han pe a ko nifee si ohun ti enikan n
so.

(vii) Eekanna

AMI ITUMO/ALAYE
Sise ni leekanna Ikilo nip e ki o dake oro tabi fi pe akiyesi re
si nnkan kan

(viii) Owo: Ilo owo bi ona ibanisoro po. A le ju owo si eniyan pe ki o wa, bee ni o le ya owo
kan naa yii lati bun i.

AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba sewo si eniyan Ki o wa tabi ki o duro de wa
Ti a ba juwo si eniyan A n kii ni
A n dagbere fun un pe ‘O digba o se’
A n le eni naa siwaju
Ti a bay a owo si eniyan A n bu iya eni naa ni
(ix) Ete: Orisiirisii ona ni a le gba lo ete lati soro. Apeere.

AMI ITUMO/ALAYE
A le yo suti ete Lati fi saata tabi bun i
A le yo ete si enikan Lati juwe tabi so ibi ti nnkan wa

IPAROKO
Aroko je ona kan ti an gba ba ara eni soro ni aye atijo. Bi awon agba ba fe soro asiri ti eni ti
won fe so o fun ko si nitosi, tabi ti won ba fe ranse sile ni asiri, aroko ni won n lo. Aroko pipa
ranse si ni ko gba sise alaye repete. Aroko ni yoo tumo ara re fun eni ti a ba ran an si.

Die ninu egbaagboje ona ti awon baba-nle wa n gba paroko ranse si eniyan ni wonyii:

(i) Ilu Lilu: Ni ile Yoruba, ilu n koi pa pataki ninu ona ibanisoro ni aye atijo. Ko si ohun ti won
ko le fi wi. Ilu ni awon baba-nla wa fi maa n ranse si oju ogun. Bi ogun bag bona janjan, ilu ni
won n ki awon asaaju.

(ii) Edan Ogboni: Edan je orisii opa Ogboni kan ti o maa n ni ere ni ori re. bi enikan ba je
gbese, ti won wa fi edan Ogboni ranse sii, eni naa ko gbodo jafara bi o bat i rii gba. O ni lati
wa owo na san kiakia. Eyi je asa larin awon Egba.

(iii) Opa Ase: Oba nikan ni o n fi opa ase paroko. Nitori pe kii se gbogbo ode ni Oba le e lo,
opa ase yii ni Oba maa n gbe ranse lati fi han wi pe oun wa nibe. Bi Oba bas i fe ri enikan ni
kiakia, opa ase ni yoo fi ranse sii.

(iv) Irukere: Oba, Baale, Ijoye ati agba-awo ni won n fi irukere paroko. Ti won bay o eyo irun
irukere kan, ki won ta ni koko si inu aso pupa, ti won ba fi ranse si enikan, apeere ija tabi
wiwa pipon onu eni tabi pe ija n bo niyi.

(vi) Awo Edun


(vii) Sigidi
(viii) Iye Adie
(ix) Ebiti ati Awo Ehoro
(x) Owo-Eyo Meta
(xi) Aso Ibora
(xii) Igbale
(xiii) Eepo igi ose ati aso pupa
(xiv) Idaji agbe emu tabi ajadii agbe
(xv) Esun-isu
(xvi) Igi sisa loge
(xvii) Morinwo tabi Aso Pupa
(xviii) Eni
(xix) Eeru

Awon aroko to je mo Onka: Iwonyi ni awon ami aroko to je mo onka Yoruba. Apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Eeta Ti a ba fi nnkan meta ranse si eniyan, o tumo si pe a ta onitohun danu.
Aarun-un Awon onifa ni won n lo lati so fun eni naa ki o se kankan lori ohun ti o
mu ni paroko naa ki ojo marun-un to pe
Eefa Ami ife ni eyi n toka si. Okunrin le fi ranse si obinrin pe ki awon fi ara
mora.
Eeje Ojo ije egungun ati oro. O tun le tumo sip e ki eni ti a paroko ranse si ri
ni ki ojo meje to pe
Eejo Bi a ba fi nnkan mejo paroko ranse sin i, to ba je owo-eyo, o tumo si pe
ko si ewu loro eni naa nitori ile jo
Eesan-an Ami ki eniyan so ewe agbeje mowo niyi, paapaa si eni to n du oye. A fi
so fun un pe “Ilesanmi dun ju oye lo”.
Eewaa Ti a ba fi owo-eyo mewaa ranse si eeyan, o tumo sip e ki o wa. Won ni
“Eewaa kii wa eni tire ti.”

Awon aroko to je mo awo

Awo Ohun to duro fun


Funfun Nnkan mimo/alaafia
Dudu Nnkan buburu. Obinrin to n sofo maa n wo aso dudu
Pupa Ohun to lewa. Pupo ni aso orisa Sango ati Esu

Awon aroko to je mo iro: Awon ohun elo ibanisoro ni a fi n gbe iro jade niwonyii:

Ohun-elo Alaye ilo won


Fere Fere le je eyi ti a fi irin, igi tabi iwo eran se. orisii fere to wa ni: Pakuta,
Anbere, Tioko, Kakaki, Turumagbe, Talaka, Ekuku, Ti-an-ko, Iwo ati bee
bee lo.
(i) Awon ode n fon ekutu ati tioko laarin ara won
(ii) Won n lo fere lati pe ara won ni igbe ode
(iii) Won n fon kakaki lati fi ki Oba ni Aafin
Agogo Orisii agogo lo wa:
(i) Alagogo Oba maa n lu u lati fi pe eniyan jo lati jise Oba
(ii) Agogo orun aja ni lati mo ibi ti aja ode wa ninu igbo
(iii) Agogo ifa ati ilu aran tabi ipese ni awon awo n lo ki ohun
didun le jade
(iv) Agogo ode asode ni lati kede pea won ti gbode
B. IBANISORO AYE ODE ONI

Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si
so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n
ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n
danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.

Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi
n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero.
Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:

(i) Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o
koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859.
Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas
je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko”
jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
(ii) Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan.
Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri
aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa
Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n
waye.
(iii) Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan
ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero
won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
(iv) Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri
oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-
oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati
diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni
ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
(v) Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-
tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
(vi) Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta,
gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu
naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat
u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
(vii) Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun
naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A
le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
(viii) Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona
ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
Agogo ile isin lilu - lati pe eeyan wa josin ni soosi
Agogo omo ile wa - lati fi pea won akekoo wole
Agogo onisowo - lati fi fa onibara won mora.

ISE ASETILEWA

1. So marun-un lara ona ibanisoro ti o mo


2. So awon eya ara marun-un ti a fi n ba ara eni soro
3. Daruko marun-un ni ara ona ibanisoro ni aye ode oni

OSE KERIN-IN

AKORI EKO: ATUNYEWO IHUN ORO

Iro konsonanti ati iro faweli pelu ami ohun ni a n hun po di oro. Orisi oro meji ni o wa ninu
ede Yoruba. Awon ni:

(i) Oro ipinle; ati


(ii) Oro ti a seda

1. ORO IPINLE: Oro ipinle ni awon oro ti a ko le seda won. Apeere:

Adie, eedu, omi, ori, oju, imu, eti, apa, ese, owo, ile, oba, odo, ojo, agbara, omo, iya ati
bee bee lo.

Abuda Oro Ipinle

(i) Oro-ipinle maa n ni itumo kikun


(ii) A ko le seda won. Bi apeere:
Iya: a ko le so pe *i+ya lo di ‘iya’
Ori: a ko le so pe *o+ri lo di ‘ori’
Omo: a ko le so pe *o+mo lo di ‘omo’
Oba: a ko le so pe *o+ba lo di ‘oba’

Oro ti a seda ati oro-ipinle awon oke yii ko ni ijora itumo. Idi niyi ti a fi pe won ni oro ipinle ti
a ko le seda rara.

2. ORO ASEDA: Eyi ni awon oro-oruko ti a seda nipa lilo afomo tabi oro miiran.

Abuda oro ti a seda

(i) Oro aseda maa n ni oro ipinle ati afomo tabi oro miiran ti a fi kun un. Apeere:
Afomo ibeere Oro-Ipinle Oro ti a seda
a + de = ade
o + re = ore

(ii) Oro ipinle ati oro-oruko ti a seda gbodo ni ijora itumo. Apeere:

Oro-Ipinle Oro ti a seda

a + de = ade

o + re = ore
(‘de’ ati ‘ade’ ni itumo ti o jade. ‘de’ tumo si ki a fi nnkan bo nnkan ni ori; ‘ade’ ohun ti a de.
‘re’ ati ‘ore’ ni ijora itumo)

ORISII ONA TI A N GBA SEDA ORO-ORUKO

A le seda oro-oruko nipa awon ona wonyii:

(i) Lilo Afomo


(a) Akanpo Afomo Ibeere ati Oro Ipinle. Akanpo bee yoo di oro-oruko. Bi apeere:

Afomo Ibeere Oro Ipinle/Oro-Ise Oro-oruko ti a seda


A Yo ayo
a se ase
o sise osise
o ku oku
ϙ gbon ogbon
ϙ re ore
ai sun aisun
ai gbagbo aigbagbo
on te onte
on kawe onkawe
ati je atije

(b) Akanpo afomo Ibeere ati ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarjoruko. Apeere:

Afomo Ibeere Mofiimu Ipinle Oro-oruko ti a seda


oni Iranu oniranu
oni eja eleja
oni aso alaso
ti emi temi
ti eyin teyin
(d) Akanpo afomo ibeere ati oro ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarajoruko. Apeere:

Afomo Ibeere Oro-Ise Oro-Ise Oro-oruko ti a seda


A Da ko adako
i tan je itanje
i gba la igbala
(e) Lilo Afomo Aarin: ‘ki’, ‘de’, ‘ku’, ‘si’ ni aarin apetunpe oro ipinle to je oro-oruko.
Apeere:

Mofiimu Ipinle Afomo aarin Mofiimu ipinle Oro-oruko ti a seda


Ile Si ile ilesile
owo de owo owodowo
iran de iran irandiran
oro ki oro orokoro
iwa ki iwa iwakiwa
eniyan ki eniyan eniyankeniyan

(ii) Sise Apetunpe Kikun. Eyi le waye nipa:

(a) Apetunpe Oro-Oruko

Oro-Oruko Oro-Oruko Oro-oruko ti a seda


iya iya Iyaaya
ose ose Osoose
odun odun Odoodun
osu osu Osoosu
ogorun-un ogorun-un Ogoogorun-un
(b) Apetunpe Apola-Ise

Apola – Ise Apola – Ise Oro-oruko ti a seda


jaye jaye jayejaye
gbomo gbomo gbomogbomo
wole wole wolewole
pana pana panapana
(d) Apetunpe Elebe: Eyi n waye ti a ba fe dunrun mooro-ise. A o so oro-ise to je mofiimu
ipinle di meji, ki a way o faweli ara oro-ise akoko sonu, a o wa fi faweli ‘i' olohun oke
ropo re. bi apeere:

Oro – Ise Konsonanti to bere oro – ise Mofiimu ‘i' Oro-oruko ti a seda
Ra R i rira
ka k i kika
bi b i bibi
we w i wiwe
(iii) Sise Akanpo Oro – Oruko. eyi le waye nipa:

(a) Akanpo oro-oruko meji inu eyi ti aranmo yoo ti han

Oro – oruko Oro – oruko Oro-oruko ti a seda


owo ile owoole
ona ile onaale
agbo ile agboole
ewe obe ewebe
(b) Abranpo Oro-oruko meji inu eyi ti aranmoyoo ti han

Oro – oruko Oro – oruko Oro-oruko ti a seda


ara Iwaju araawaju
enu ona enuuna
irun agbon irungbon
(d) Akanpo Afomo Ibeere ati Apetunpe Oro-Oruko. Apeere:

Afomo Ibeere Oro – Oruko Oro – Oruko Oro-oruko ti a seda


oni ojumo ojumo olojoojumo
oni osu osu olosoosu

(e) Akanpo Afomo Ibeere ‘oni’ mo oro-oruko meji. apeere

Afomo Ibeere Oro – oruko Oro – Oruko Oro-oruko ti a seda


oni ori ire oloriire
oni aya oba alayaa
(iv) Sise asunki odidi gbolohun di oro-oruko. apeere

Gbolohun Oro-oruko ti a seda


Oluwa to sin Oluwatosin
A kuru yejo Akuruyejo
(v) Siso oro-oruko onigbolohun po. Apeere:

Ifa ni eti - Faleti


Oye ba mi ji - Oyebamiji
Aje wo ile - Ajewole
(vi) Lilo ami asoropo oro onigbolohun. Apeere

a-duro-sigidi-koogun-o-je
a-losoo-gongo-je’su-eba-ona.

ISE AMUTILEWA

1. Se itupale akojopo oro-oruko eniyan ti a seda wonyii:


(i) Faleti
(ii) Omolola
(iii) Ifeolu
(iv) Titilayo
(v) Ilesanmi
(vi) Iluyomade
(vii) Adeoti
(viii) Olukoyejo
(ix) Adeyemi
(x) Oladiran
2. Pin awon oro-oruko wonyi si eyi ti a seda ati eyi ti a ko seda
(i) Igunpa
(ii) Imu
(iii) Aso
(iv) Oguntoye
(v) Oko
(vi) Ese
(vii) Oju
(viii) Inufele
(ix) Erupe
(x) Eti

AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO

Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye
won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti
won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.

Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa
loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro
lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran
paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.

Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba.
Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.

IBANISORO AYE ODE ONI

Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si
so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n
ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n
danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.

Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi
n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero.
Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:

(i) Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o
koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859.
Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas
je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko”
jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
(ii) Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan.
Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri
aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa
Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n
waye.
(iii) Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan
ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero
won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
(iv) Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri
oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-
oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati
diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni
ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
(v) Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-
tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
(vi) Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta,
gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu
naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat
u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
(vii) Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun
naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A
le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
(viii) Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona
ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
Agogo ile isin lilu - lati pe eeyan wa josin ni soosi
Agogo omo ile wa - lati fi pea won akekoo wole
Agogo onisowo - lati fi fa onibara won mora.
OSE KARUN-UN

AKORI EKO: ONKA YORUBA (EGBAA de AADOTA OKE)


Igba mewaa (200 x 10) ni a n pe ni egbaa. A le wa ka a bayii:

Onka Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba Alaye ni Geesi


2,000 Egbaa Igba lona mewaa 2,000 x 1
4,000 Egbaaji Igba lona ogun 2,000 x 2
6,000 Egbaata Igba lona ogbon 2,000 x 3
8,000 Egbaarin Igba lona ogoji 2,000 x 4
10,000 Egbaarun-un Igba lona aadota 2,000 x 5
12,000 Egbaafa Igba lona ogota 2,000 x 6
14,000 Egbaaje Igba lona aadoje 2,000 x 7
16,000 Egbaajo Igba lona ogoje 2,000 x 8
18,000 Egbaasan-an Igba lona aadorun-un 2,000 x 9
20,000 Egbaawaa (oke kan) Igba lona ogorun-un 2,000 x 10

E je ki a lo egbaa lati se onka nipa fifi egbaa pin iye onka ti a ba fe ka, ji a to maa kaa loke
loke.

Onka Alaye ni Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba


Geesi
30,000 2,000 x 15 Egbaa meedogun Egbaa lona meedogun
32,000 2,000 x 16 Egbaa merindinlogun Egbaa lona merindinlogun
34,000 2,000 x 17 Egbaa metafinlogun Egbaa lona metadinlogun
36,000 2,000 x 18 Egbaa mejidinlogun Egbaa lona mejidinlogun
38,000 2,000 x 19 Egbaa mokandinlogun Egbaa lona mokandinlogun
42,000 2,000 x 21 Egbaa mokanlelogun Egbaa lona mokanlelogun
44,000 2,000 x 22 Egbaa mejilelogun Egbaa lona mejilelogun
46,000 2,000 x 23 Egbaa metalelogun Egbaa lona metalelogun
48,000 2,000 x 24 Egbaa merinlelogun Egbaa lona merinlelogun
52,000 2,000 x 26 Egbaa merindinlogbon Egbaa lona merindinlogbon
54,000 2,000 x 27 Egbaa metadinlogbon Egbaa lona metadinlogbon
56,000 2,000 x 28 Egbaa mejidinlogbon Egbaa lona mejidinlogbon
58,000 2,000 x 29 Egbaa mokandinlogbon Egbaa lona mokandinlogbon

‘o din’ tabi ‘o le’ ni a o maa lotiti de ori onkaye ta a n fe. Bi apeere: 30,400 je egbaa
meedogun o la irinwo, 51,000 ni egberundilogbon; 57,991 je egbaa mokandinlogbon o din
mesan-an; 58,008 je egbaa mokandinlogbon o le mejo. Lati ori 20,000, a le wa ma aka oke
bayii:

Onka Geesi Alaye ni Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba


40,000 20,000 x 2 Oke meji Oke lona meji
60,000 20,000 x 3 Oke meta Oke lona meta
80,000 20,000 x 4 Oke merin Oke lona merin
100,000 20,000 x 5 Oke marun-un Oke lona marun-un
120,000 20,000 x 6 Oke mefa Oke lona mefa
140,000 20,000 x 7 Oke meje Oke lona meje
160,000 20,000 x 8 Oke mejo Oke lona mejo
180,000 20,000 x 9 Oke mesan-an Oke lona mesan-an
200,000 20,000 x 10 Oke mewaa Oke lona mewaa
220,000 20,000 x 11 Oke mokanla Oke lona mokanla
240,000 20,000 x 12 Oke mejila Oke lona mejila
260,000 20,000 x 13 Oke metala Oke lona metala
280,000 20,000 x 14 Oke merinla Oke lona merinla
300,000 20,000 x 15 Oke meedogun Oke lona meedogun
400,000 20,000 x 20 Ogun oke Oke lona ogun
500,000 20,000 x 25 Oke marundinlogbon Oke lona marundinlogbon
600,000 20,000 x 30 Ogbon oke Oke lona ogbon
800,000 20,000 x 40 Ogoji oke Oke lona ogoji
1,000,000 20,000 x 50 Aadota oke Oke lona aadata

Bi a se n lo ‘o din’ ni kika egbaalegbaa naa ni a n lo ‘o din’ ati ‘o le’ ti a ba n ka lokeelokee. Bi


apeere:

Onka Geesi Alaye ni Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba


20,080 20,000+1 = 80 Orin le l’oke kan Oke kan o le ogorin
40,008 20,000+2 = 8 Oke meji le mejo Oke meji ati eeyo mejo
40,060 20,000x2 + 60 Otalelokee meji Oke meji o le ogota
43, 000 20,000x2 + 3,000 Oke meji le legbeedogun Oke meji ati egbeedogun
47,000 20,000x2 + 7,000 Oke meji le leeedegbaarin Oke meji ati eedegbaarin
49,000 20,000x2 + 9,000 Oke meji le eedegbaarun-un Oke meji ati egbaarun-
51,000 20,000x2 + 11,000 Oke meji o le eedegbaafa un
55,000 20,000x2 + 15,000 Oke meji o le eegbaajo Oke meji ati egbaafa o din egberun

57,000 20,000x2 + 17,000 Oke meji o le eedegbaasan-an Oke meji ati edegbaajo
59,000 20,000x2 + 19,000 Oke meji le eedegbaawaa Oke meji ati eedegbasan
Oke meji ati eedegbawa

ISE AMUTILEWA

1. Ko onka awon figo wonyi:


(i) 30,000
(ii) 35,000
(iii) 36,000
(iv) 47,000
(v) 52,000
(vi) 600,000
(vii) 750,000
(viii) 850,000
(ix) 950,000
(x) 1,000,000

AKORI EKO: ORISA ILE YORUBA

OGUN

ITAN NIPA OGUN


Ogun je okan pataki ninu awon okanlenirinwo irunmole ti won ti ikole orun wa si ile aye. A
gbo pe nigba ti awon orisa n bo wa si ile aye, won se alabaapade igbo didi kijikiji kan. Orisa-
Nla ni a gbo pe o koko lo ada owo re lati la ona yii sugbon ada fadaka owo re se. Ogun ni a
gbo wi pe o fi ada irin owo re la ona gberegede fun awon orisa yooku lati koja. Ise ribiribi ti
ogun se yii ni awon orisa yii se fi jeoye Osin-Imole ni ile-Ife.

Itan fi han pe ode to ni okiki ni ogun. Tabutu ni oruko iya re. Baba re ni Ororinna. Won ni
Ogun feran ise ode sise to bee to fi fi ilu sile lo si ori-oke kan ki o le ri aaye se ise ode. Igba ti
ori-oke yii su un ni o pinnu lati pada si Ile-Ife. Igba ti ogun n bo, oju re le koko. Won ni:

‘Ojo Ogun n ti ori oke e bo,


Aso ina lo mu bo ‘ra,
Ewu eje lo wo sorun’.
Eyi ti Ogun iba fi duro ni Ile-Ife, ilu Ire ni a gbo pe Ogun lo. Won si gba a tayotayo. A gbo pe
emu ni Ogun ko beere nigba ti o de Ire. Won fun un ni ounje ati emu mu. Idi niyi ti won fi n
so pe: ‘Ire ki i se ile Ogun, o yak i won nibe menu ni’. Ori oke ninu igbo kan ni Ogun tun lo
do sin i Ire. Bi o ba n bow a si aarin ilu, mariwo ni o maa n fi bora. Idi niyi ti won fi n ki i ni:
‘O-laso-nile fimokimo bora, Mariwo yegbeyegbe laso ogun’.

Orisirisi oruko ni won n pe Ogun. Ogun ni won tun n pen i Lakaaye; Osinmole, Awoo,
Olumokin, Yankanbiogbe ati bee bee lo.

IGBAGBO YORUBA NIPA OGUN

(i) Ogun ni orisa to ni irin. Gbogbo awon ti won n fi irin se je ti ogun.


(ii) Oun lo la ona fun awon orisa elegbe re
(iii) Orisa to feran ododo ati otito
(iv) Orisa ogun ni Ogun
(v) Gbenagbena ni Ogun

ODUN OGUN
Kari ile Yoruba ni won ti n se odun Ogun, sugbon o gbayi ju lo ni awon ilue bii Ondo, Ilesa,
Ile-Ife, Akure ati Ekiti. Akoko isu titun ninu osu keje si ikejo odun ni won n se odun Ogun.Ilu
Agere, Katakoto ati bembe ni ile Ogun.

AWON OHUN TI WON FI N BO OGUN

Aja, Esun isu, epo, adiye, agbo, ewure, eyele, igbin, ewa eyan, iyan, obi abata, orogbo,
ataare ati emu. Eekan soso ni apaja ogun gbodo be aja ni orun ti won ba n bo Ogun.

OJUBO OGUN

Awon ohun ti a n ri ni ojubo orisa yii ni omo owu, opa ogun, emu sekele, ada, ibon,obe, irin,
olugbondoro, awon nnkan ija ogun.

BI WON SE N BO OGUN

Bi won se n bo Ogun ilu naa ni won n bo Ogun idile kookan. Okuta ribiti lo duro fun Ogun
Agbede. Ori re ni awon alagbede ti n ro oko ati ada. Irin wewe ti a ko jo sinu ate Ogun lo
duro fun ‘Ogun Ate’.

ORIKI OGUN

Ogun lakaye. Osin Imole


Ogun alada meji
O fi okan san’ko
O fi okan ye’na.
Ojo ogun n ti ori oke bo
Aso ina l’o mu bora
Ewu eje lo wo.
Ogun onile owo, olona ola
Ogun onile kangunkangun orun
O pon omi s’ile f’eje we
Ogun awon l’eyinju’
Egbe l’ehin omo kan,
Ogun meje l’ogun mi,
Ogun alara ni igba ‘ja,
Ogun Onire a gbagbo
Ogun ikola a gba’gbin
Ogun Elemona ni i gba esun’su
Ogun Aki’run a gba iwo agbo
Ogun Gbenagbena eran awun ni i je
Ogun Makinde ti d’Ogun l’ehin odi,
Bi ko ba gba Tapa, gb’Abooki,
Agba Uku-uku, agba Kemberi,
Nje nibo l’a ti pade Ogun?
A pade Ogun nibi ija,
A pade Ogun nibi ita;
A pade re nibi agbara eje n san,
Agbara eje ti i de ni lorun bi omi ago
Orisa t’o ni t’Ogun ko to nkan
A f’owo je’su re nigba aimoye…

OSE KEFA

AKORI EKO: ITESIWAJU ONKA YORUBA


Igba mewaa (200 x 10) ni a n pe ni egbaa. A le wa ka a bayii:

Onka Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba Alaye ni Geesi


2,000 Egbaa Igba lona mewaa 2,000 x 1
4,000 Egbaaji Igba lona ogun 2,000 x 2
6,000 Egbaata Igba lona ogbon 2,000 x 3
8,000 Egbaarin Igba lona ogoji 2,000 x 4
10,000 Egbaarun-un Igba lona aadota 2,000 x 5
12,000 Egbaafa Igba lona ogota 2,000 x 6
14,000 Egbaaje Igba lona aadoje 2,000 x 7
16,000 Egbaajo Igba lona ogoje 2,000 x 8
18,000 Egbaasan-an Igba lona aadorun-un 2,000 x 9
20,000 Egbaawaa (oke kan) Igba lona ogorun-un 2,000 x 10

E je ki a lo egbaa lati se onka nipa fifi egbaa pin iye onka ti a ba fe ka, ji a to maa kaa loke
loke.

Onka Alaye ni Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba


Geesi
30,000 2,000 x 15 Egbaa meedogun Egbaa lona meedogun
32,000 2,000 x 16 Egbaa merindinlogun Egbaa lona merindinlogun
34,000 2,000 x 17 Egbaa metafinlogun Egbaa lona metadinlogun
36,000 2,000 x 18 Egbaa mejidinlogun Egbaa lona mejidinlogun
38,000 2,000 x 19 Egbaa mokandinlogun Egbaa lona mokandinlogun
42,000 2,000 x 21 Egbaa mokanlelogun Egbaa lona mokanlelogun
44,000 2,000 x 22 Egbaa mejilelogun Egbaa lona mejilelogun
46,000 2,000 x 23 Egbaa metalelogun Egbaa lona metalelogun
48,000 2,000 x 24 Egbaa merinlelogun Egbaa lona merinlelogun
52,000 2,000 x 26 Egbaa merindinlogbon Egbaa lona merindinlogbon
54,000 2,000 x 27 Egbaa metadinlogbon Egbaa lona metadinlogbon
56,000 2,000 x 28 Egbaa mejidinlogbon Egbaa lona mejidinlogbon
58,000 2,000 x 29 Egbaa mokandinlogbon Egbaa lona mokandinlogbon
‘o din’ tabi ‘o le’ ni a o maa lotiti de ori onkaye ta a n fe. Bi apeere: 30,400 je egbaa
meedogun o la irinwo, 51,000 ni egberundilogbon; 57,991 je egbaa mokandinlogbon o din
mesan-an; 58,008 je egbaa mokandinlogbon o le mejo. Lati ori 20,000, a le wa ma aka oke
bayii:

Onka Geesi Alaye ni Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba


40,000 20,000 x 2 Oke meji Oke lona meji
60,000 20,000 x 3 Oke meta Oke lona meta
80,000 20,000 x 4 Oke merin Oke lona merin
100,000 20,000 x 5 Oke marun-un Oke lona marun-un
120,000 20,000 x 6 Oke mefa Oke lona mefa
140,000 20,000 x 7 Oke meje Oke lona meje
160,000 20,000 x 8 Oke mejo Oke lona mejo
180,000 20,000 x 9 Oke mesan-an Oke lona mesan-an
200,000 20,000 x 10 Oke mewaa Oke lona mewaa
220,000 20,000 x 11 Oke mokanla Oke lona mokanla
240,000 20,000 x 12 Oke mejila Oke lona mejila
260,000 20,000 x 13 Oke metala Oke lona metala
280,000 20,000 x 14 Oke merinla Oke lona merinla
300,000 20,000 x 15 Oke meedogun Oke lona meedogun
400,000 20,000 x 20 Ogun oke Oke lona ogun
500,000 20,000 x 25 Oke marundinlogbon Oke lona marundinlogbon
600,000 20,000 x 30 Ogbon oke Oke lona ogbon
800,000 20,000 x 40 Ogoji oke Oke lona ogoji
1,000,000 20,000 x 50 Aadota oke Oke lona aadata

Bi a se n lo ‘o din’ ni kika egbaalegbaa naa ni a n lo ‘o din’ ati ‘o le’ ti a ba n ka lokeelokee. Bi


apeere:

Onka Geesi Alaye ni Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba


20,080 20,000+1 = 80 Orin le l’oke kan Oke kan o le ogorin
40,008 20,000+2 = 8 Oke meji le mejo Oke meji ati eeyo mejo
40,060 20,000x2 + 60 Otalelokee meji Oke meji o le ogota
43, 000 20,000x2 + 3,000 Oke meji le legbeedogun Oke meji ati egbeedogun
47,000 20,000x2 + 7,000 Oke meji le leeedegbaarin Oke meji ati eedegbaarin
49,000 20,000x2 + 9,000 Oke meji le eedegbaarun-un Oke meji ati egbaarun-
51,000 20,000x2 + 11,000 Oke meji o le eedegbaafa un
55,000 20,000x2 + 15,000 Oke meji o le eegbaajo Oke meji ati egbaafa o din egberun

57,000 20,000x2 + 17,000 Oke meji o le eedegbaasan-an Oke meji ati edegbaajo
59,000 20,000x2 + 19,000 Oke meji le eedegbaawaa Oke meji ati eedegbasan
Oke meji ati eedegbawa

ISE AMUTILEWA

2. Ko onka awon figo wonyi:


(xi) 30,000
(xii) 35,000
(xiii) 36,000
(xiv) 47,000
(xv) 52,000
(xvi) 600,000
(xvii) 750,000
(xviii) 850,000
(xix) 950,000
(xx) 1,000,000

AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA

ORUNMILA

ITAN NIPA ORUNMILA


Okan pataki ni Orunmila je ninu awon okanlenirinwo Irunmole ti won ti ikole orun ro si Ofe
Oodaye. Ni Oke Igbeti ni Orunmila koko de si ki o to lo si Oke Itase. Idi niyi ti won fi n ki i ni
‘Okunrin kukuru Oke Igbeti’.

Orunmila ni alakoso Ifa dida ati tite ile. Owo re ni akoso aye nipa ogbon ati imo ohun ti yoo
sele lojo iwaju wa. Ko si oro kan ni abe orun tabi oro kan nipa isenbaye, ogbon ati igbagbo
awon Yoruba ti Ifa ko so nipa re.

Gege bi Ojogbon ‘Wande Abimbola ti so ninu iwe “Awon Oju Odu Mereerindinlogun”,
Orunmila lo opolopo odun ni Ife Oodaye, ki o to lo si Ado, ibi ti o ti pe ju lo ni ode aye. Idi
niyi ti won fi n so pe ‘Ado n’ile Ifa’. Orunmila tun gbe ni Otu Ife.ibe ni o ti bi awon omo
wonyi: Alara, Ajero, Owarangun-aga, Oloyemoyin, Ontagi-olele, Elejelu-mope ati Olowo.
O tun gbe ni Ode Oyan, ibi to ti bi Amukanlode-Oyan. Bakan naa ni o gbe ni ode Onko, to ti
bi Amosunlonkoegi.

Out-Ife ni itan so pe Orunmila ti pada si ode orun, ti ko si was i aye mo nitori iwa arifin ti
Olowo, abikeyin omo re ni Otun Ife hu si i ni ojo ti Orunmila se odun. Orunmila ranse si
awon omo re pe ki won w aba oun se odun. Bi won ti n de ni won n fori kanle ni okookan, ti
won n so wi pe ‘aboruboye bo sise’. Igba ti Olowo de, o duro, o ni oun ko le wi ‘aboruboye
bo sise’. Orunmila beere idi to fi se bee, Olowo ni:

“Iwo Orunmila sodun, o sodun ko;


Oun Olowo naa sodun, oun sodun ko
Iwo Orunmila f’osun ide lowo;
Oun Olowo naa f’osun ide lowo
Iwo bo salubata ide
Oun Olowo bo salubata ide…..
Iwo Orunmila dade
Oun Olowo naa dade,
Bee ni won sin i
Enikan ki i fori ade bale fenikan…..”
Oro yii lo mu Orunmila binu gba Osun Ide owo Olowo, o kori si idi Ope Agunka, ibe ni o gba
lo si orun. Nigba ti Orunmila lo tan ni gbogbo nnkan daru, aye ko roju mo. Gbogbo aye lo be
awon omo Orunmila ki won ba won be baba won. Igba ti won de idi ope agunka ti Orunmila
do si, won be e titi, Orunmila da won lohun pe oun ko tun pada wale aye mo. O wa fun won
ni ikin merindinlogun, ti o fi ropo ara re. O ni:

B’e e ba dele
B’e e f’owoo ni
Eni t’e e moo bi nu-un….
Lati igba naa ni ikin ti di ohun elo pataki ti awon babalawo fi n beere nnkan lowo Orunmila.

IGBAGBO YORUBA NIPA ORUNMILA

(i) Orunmila alakoso Ogbon, Imo ati Oye


(ii) Opitan ni Orunmila
(iii) Okunrin Kukuru Dudu ni Orunmila
(iv) Orunmila ni alakoso Ifa dida ati tite ale
(v) Orunmila ko ni egungun lara lati sise agbara
(vi) Agbaye-gborun ni Orunmila

BI WON SE N BO ORUNMILA

Ojo awo ni won bo Orunmila, bi o tile je wi pe ojoojumo ni awon babalawo n bo Ifa. Bi won
se n difa oroorun naa ni won n se odun Ifa ni odoodun.

Ti won ba fe bo Ifa ni owuro, babalawo yoo mu obi si inu omi tutu, yoo maa fi iroke lu opon
Ifa, yoo maa ki Orunmila ni mesan-an-mewa. Babalawo yoo pa obi naa, yoo se oju yii si inu
omi. Omi naa ni yoo lo da fun Esu. Babalawo yoo wa da obi naa mo bi Ifa ba gba a. bi obi
bay an tako tabo, iyen ti meji si oju, ti meji da oju de ile, Ifa ti gba obi nu un. Babalawo yoo
pin obi fun awon to wa nibe lati je.

Bi o ba je Ifa odun, awon nnkan repete ni won yoo ka sile. Won yoo sip e mutumuwa fun
ariya.

OHUN TI WON FIN N BO IFA

Eku meji, Eja meji, Igbin, Ewure, Adiye, Isu, Aguntan, Osuka omu ati obi.

AWON OHUN ELO IFA

Opele, Apo Ifa, Iroke Ifa, Opon Ifa.

Opon-Ifa ti a fin ona si lara, Iyerosun, Iroke, Ibo, Opele, Ikin merindinlogun, Awo-Ifa, Opa
Osooro, Irukere.
SANGO: ITAN SANGO
Eniyan ni a gbo pe Sango je ki o to di orisa. Sango je orisa ti ise, irisi ati isoro re kun fun
iberu. Sango je omo Oranmiyan. Awon iyawo re ni Oya, Osun ati Oba.

Itan so nipa Sango pe o je Oba l’ode Oyo-ile. Gege bi Oba alagbara, onigboya to tun loogun,
o feran lati maa fi agbara re han awon eniyan. Bi Sango ba n soro ina a maa jade ni enu re.
Ijoye tabi ara ilu to ba ni ti Sango bawo yoo je iyan re ni isu. A gbo pe Sango lo da ija sile
laarin ijoye ilu meji, ti okan fi pa ekeji ku fininfinin.

Bayii ni Sango n da ilu ru, ti tomode-tagba ilu fi dite mo on. Igba ti ote yii kojaa siso, Sango ko
eru re, o sa kuro l’ode Oyo. Awon iranse re, Osumare ati Oru pada leyin re. sugbon awon
iyawi re meteeta n tele leyin lai mo ibi kan pato ti won n lo. Igba ti Sango rin die si Oyo, to ri
pe oun ko leni lehin mo, afi Oya, ironu mu un, o way a si idi Igi Ayan, o si so ara re mo ibe, ti
a n n pe ni Koso. Oya, iyawo re sa lo si apa ariwa, wole ni Ira, o si di odo Oya. Awon ero ti n
koja ri Sango, won n yo suti ete si i pe ‘Oba so!, Oba so!’. Oro yii ko dun moa won eniyan
Sango ninu, won si yo kelekele lo si ilu Ibariba lati gba oogun buburu ti won fi n baa won ota
Sango ja. Igba miiran, won a yo kelekele fi in abo ile ni orun, won a ni Sango lo n binu. Ti ojo
ba ro ti ara san, ti ‘edun ara’, ti o je okuta ba pa eniyan, won a ni Sango lo n binu. Idi niyi ti a
se n pe Sango ni ‘Jakuta’. Igba ti wahala yii po ni awon ara Oyo bay i ohun pada, won n so pe
‘Sango Oba Koso’, ki won ma baa ri ibinu re. iberu yii ni won fi so Sango di orisa titi di oni.

Ilu Oyo ni odun Sango ti gbayi julo ni ile Yoruba. Won tun n se odun re ni Ibadan, Iseyin, Iwo,
ede, Abeokuta, Ilesa, Ondo ati Ekiti. Awon aworo re ni a n pe ni Onisango tabi Adosun-
Sango. Awon asaaju won ni a n pe ni Magba tabi Iya Magba. Adosun-Sango maa n di irun ori,
won n wo aso osun ti Sango feran ju lo nigba aye re. Awon aworo re maa n mu Ose Sango
lowo. Ilu bata ni ilu Sango Ounje ti Sango feran ni amala pelu obe eweedu, eran agba,
orogbo ati obi. Idi niyi ti won fi n ki i ni: Sango oloju Orogbo, eleeke Obi.

IGBAGBO YORUBA NIPA SANGO

(i) Orisa to ni agbara lori ara ati imonamona


(ii) Orisa afajo
(iii) O n fun won lomo

AWON OHUN ELO SANGO: Bata, ilu Sango, Ose Sango, Sere Sango, Laba Sango

OHUN TI WON FI N BO SANGO: Orogbo ni obi Sango. Won n fi oka, adiye ati aguntan bolojo
bo. Ounje Sango ni oka.

ORIKI

Penpe bi asa, asode bi Ologbo


Sangiri-lagiri!
Olagiri kaka f’igba edun bo o!
Eefin ina l’a nda l’aiye
Ina mbe l’odo oko-mi orun
Sango Onibon orun
Ajalaji Oba Koso
Ewelere okoo mi
Aara-sowo-ija-lala!
Aara-o-fija-wole!.....

OSE KEJE

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA ARA IFO


“Eya ara ifo ni awon orisirisii eya ara ti a maa n lo fun pipe iro ede”.

Abuda kan pataki ti o ya awa eniyan soto si awon eda yooku ni ebun oro-siso. Bi apeere, ti a
ba so wi pe ‘Bawo ni nnkan’, awon eya ara kan wa ninu ara wa lati ori de ikun ti won jumo
sise papo lati gba gbolohun ibeere yii jade. Awon eya ara bee ni a n pe ni eya-ara ifo.
Aworan eye-ara ifo naa niyi:

AWORAN EYA-ARA IFO

ISORI EYA-ARA IFO

A le pin awon eya-ara ifo si eya meji. Awon ni:

(i) AWON EYA-ARA IFO AFOJURI: Awon wonyi ni eya-ara ifo ti a le fi oju ri nipa lilo digi tabi
nnkan miiran. Awon naa ni:

Afase, Olele, Iho imu Ita gogongo, Ete oke, Ete isale, Eyin oke, Eyin isale, Iwaju ahon, Aarin
ahon, Eyin ahon, Erigi, Ajaa enu.

(ii) AWON EYA-ARA IFO AIFOJURI: Awon wonyi ni awon eya-ara ifo ti won wa lati inu ikun si
inu ofun ti a ko le fi oju ri rara. Awon ni:

Kaa ofun, inu gogongo, Tan-an-na ofun, komookun, Eka komookun, Edo-foro.

S/N EYA-ARA IFO APEJUWE ILO WON


1. Komookun Edo-foro: Inu edo-foro ni eemi ti a n lo fun opo iro ede ti
n tu jade sita. Eyi ni a n pe ni eemi edo-foro. Eran ara
edo-foro maa n fe lati pese eemi amisinu tabi amisode
fun oro siso.

2. Edo foro Komookun ati Eka komookun: inu eka komookun mejeeji
ati komookun ni eemi edo-foro n gba koja si inu gogongo
ati enu.
3. Gogongo Ori komookun tente ni gogongo dabuu le ni ofun. A le ri
ita gogongo ni ofun wa.
4. Tan-an-na ati Alafo Inu gogongo ni tan-an-na wa. Inu alafo tan-an-na yii ni
Tan-an-na eemi edo-foro n gba jade si ona ofun.
5. Kaa Ofun, Kaa Enu Oke tan-an-na ni awon kaa meteeta wonyi wa. Ona ikoja
ati Kaa Imu ni won je fun eemi yala eemi amisinu tabi amisode
6. Ahon Ahon je eya ara lo n kopa julo pipe iro ifo nitori pe o se e
gbe si orisiirisii ipo. A le pin ahon si apa meta wonyi:
(i) Iwaju ahon
(ii) Aarin ahon
(iii) Eyin ahon
7. Ete A le paete po pekipeki; ete le fe seyin perese, tabi ki a su
won po roboto. Idi niyi ti a fi n ni iro faweli perese tabi
roboto.
8. Afase Ni enu, afasa le gbera soke tabi wale fun eemi lati ri aaye
gba kaa imu tabi enu jade. Idi niyi ti a fi n ni iro aranmupe
tabi iro airanmupe.
9. Eyin oke, Erigi, Aja- Afipe akanmole ni won. A n lo won po mo afipe asunsi
enu lati pe iro. A n lo eyin-oke papo mo ete isale tabi iwaju
ahon pelu arigi ati aja-enu.

AFIPE: Afipe ni eya ara yoowu ti o ba n kopa ninu iro pipe.


Afipe ni gbogbo awon eya ara-ifo ti won wa lati oke alafo tan-an-na ofun de enu ati imu.
Aarin yii ni a n pe ni opona ajemohun.

A le pin awon eya-ara ifo ti eon je afipe si meji. Awon ni:

(a) Afipe asunsi; ati


(b) Afipe akanmole

AFIPE ASUNSI: Afipe asunsi ni awon eya ara isale enu ti won le gbera soke tabi sodo lati sun
kan afipe akanmole ti a ba n pe iro. Awon ni: Olele, Ete isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin
ahon.

AFIPE AKANMOLE: Afipe akanmole ni awon eya ara oke enu ti won n duro gbari si oju kan ti
a ba n pe iro. Awon ni: Ete oke, Ogiri ofun, Eyin oke, Afase, Aja-enu, Erigi, Kaa imu.
Awon eya-ara ifo miiran ti won wa ni opona ajemohun tun ni awon ise miiran ti won n se to
yato si oro siso. Bi apeere, imu wa fun oorun gbigbo tabi mimi; eyin wa fun ounje wiwe, bee
ni ahon wa fun tito nnkanwo. Opona ajemohun bere lati aarin oke alafo tan-an-na titi de enu
ati imu.

AKORI EKO: AWON ORISA ATI BI A SE NBO WON

IPO OLODUMARE ATI ORISA


Awon Yoruba gba wi pe enikan wa ti o ni ogbon, agbara, to si ga ju gbogbo orisa ati eda aye
lo. Eyi ni won n pe ni Olorun tabi ‘eni ti o ni orun’, ibi ti won gba gege bii ibugbe Re. Won
mo, won si gba wi pe Olorun yii ni o tobi julo. Idi niyi ti won fi pe e ni Olodumare. Oniruru
oruko ni won fun Olodumare lati fi igbagbo won han. Won ni “F’ija f’Olorun ja, f’owo leran”.
Eyi fi Olodumare han bi onidajo ododo.

Alarina tabi alagbawi lasan ni awon orisa je laaarin Olodumare ati awon eda eniyan. Iranse
Olodumare ni awon Yoruba ka won si. Olodumare ni o ran won wa si ile aye lati wa tun aye
se. Idi niyi ti awon Yoruba se fi won si ipo pataki. Igbagbo Yoruba tun re e.

(i) Awon orisa ni won le gbe ebe won de iwaju Olodumare. Won gbagbo pe nitori pe
Olodumare ga ju fun awon lati maa sun mo nigba gbogbo. Bee ni awon orisa
wonyi sun mo Olodumare niroti iranse re ni won. Bi a ba si fe gba nnkan lowo
eniyan, eni ti o ba mo oju re ni a n toju ki o le je ise wa daadaa. Idi niyi ti awon
Yoruba fi n toju awon oris, ti won fi n ko ile fun won.
(ii) Awon abami eda tabi emi buburu kan wa ti won le fi iku tabi aisan buburu je
awon niya. Won n se ebo ati etutu lorisirisi lati petu fun abami eda ati lati wa oju
rere won. Opolopo awon oke, odo, igi nla ati awon eni lile aye atijo, ti won ni eru
lara ni won ti so di orisa akunlebo, bi apeere; Sango, Oya, Ogun ati bee bee lo.
Igbagbo won ni pe awon emi buburu wonyi n gbe ori oke, abe apata, inu omi
nlaati ara igi ti o ga pupo. Bee ni awon miiran n boa won abami eranko bii Onni,
Ere tabi Ejo ati awonope ti o ba yo eka fun idi kan naa.

PATAKI ORISA LAWUJO YORUBA

Ti a ba n soro nipa orisa ile Yoruba, bi eni n soro nipa esin abalaye won ni. Awon orisa wonyi
ti di ohun ti won n bo fun awon idi ti a ti menuba. Iwonyi ni pataki awon orisa yii ni awujo
Yoruba.
(i) Imuni mo orison eni: Awon agba ni “Odo to ba gbagbe orison gbigbe ni i gbe”.
Awon orisa wonyi n je ki omo Yoruba mo esin idile won. Osagbemi, Efunkemi,
Osuntokun, Abegunde je oruko idile oloosa. Olorisa Egungun ni won n so omo
won ni Abegunde, awon Onifa ko je so omo won ni Osungbemi laelae. Awon
orisa wonyi je ki a mo ona ti a to waye, eyi si n satona ihuwasi eni ni awujo.
(ii) Ipese aabo ati ipese ire gbogbo: Bi oro ba diju, ifa ni awon Yoruba maa n fi oro lo.
O daju pe ko si nnkan ti a le fe dawole ni awujo Yoruba ti a ko ni bi Ifa. Bee naa ni
a n bo egungun ni iranti awon ara orun fun idaabobo. Bee ni ko si ebo ti a le gbe
leyin esu ki ebo naa fin.
(iii) Orisa gege bi amu eko iwa atata ati iwa-bi-Olorun: Awon orisa ile Yoruba ni eewo
to n dari ihuwasi olusin. Obatala fe mimo mimo, ohun to funfun, ni iwa, ni ero ati
ni ise. orisa Ogun ko fe iro. Idi niyi ti won fi n fi i buran i ile ejo. Orisa-Nla ko oro
iwosi, ko ni ife si aso. O ko awon olusin re pe iyawo kan soso lo dara loode. O ni
“A ko le gbe aarin oji eniyan k’a ma si wi”.
(iv) Orisa bi amu ilana akoso to to: Bi a ba wo itan iwase, bi Olodumare ti ni agbara
to, to je pee da owo re ni gbogbo awon orisa, sibe o pin ise akoso fun olukuluku
won. Orisa kookan lo n sakoso eka kookan ninu aye ti Olodumare da. Eyi je
apeere rere fun awujo w ape ki a ma da wa gbogbo nnkan mo ori. Agbara pupo n
seku pa ni. Oba nikan ko le da ilu se. awon ijoye ilu ni ojuse. Eto niyi yi a le mulo
ninu eto iselu wa.
(v) Ogun iyebiye: Ogun iyebiye ni an ri ko ni akoko odun awon orisa wonyi. Akoko
naa maa n je asiko ajoyo, ijo ati orin kiko tabi ewi kike. Irufe orin yii ti di ogun
iyebiye fun awon omo Yoruba. Awon orin bi Ijala are ode, Esa egungun, Sango
pipe ti di ilumoka. Gege bi won n gbe awon ti Olodumare ba fi ke ni ile yii ati ni
oke okun.
(vi) Amu imo fun awon onkowe: Awon onkowe n ri nnkan ko lori awon orisa fun ojo
iwaju: awon onkowe itan tabi awon to n ko ewi n menuba oriki awon orisa ninu
iwe won. Onkowe Yoruba ti ko bam o nipa awon orisa ile Yoruba ko le ko iwe to
ye kooro ninu asa. Apeere iwe to samulo awon orisa ni Oba Koso ti Duro Ladipo
ko, Obaluaye, ti Wale Ogunyemi ko. A ri i bi gbogbo awon orisa se dide pelu ija si
ilu ti ko fi tiwon se. Iwe J.S. Sowande (Sobo Arobiodu) fi imo re to jinle ninu esin
ati orisa Yoruba han ninu ewi yii fun awujo. O ni:
A ki i siwaju Olifa
A ki i siwaju Olorisa korisa
A ki i siwaju Olobatala reri ose;
A ki i siwaju Tisa liborin:
Bi a ba siwaju Tisa liborin
A ko maa gbo ki duuru kun.

ISE AMUTILEWA
1. So igbagbo Yoruba nipa orisa
2. Ko oriki awon orisa wonyi sile:
(i) Sango
(ii) Orunmila
(iii) Ogun
3. So ipa pataki ti orisa ko laarin awon Yoruba
4. So ipo Olodumare ati orisa bi igbagbo awon Yoruba.

OSE KEEJO

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON IRO NINU EDE YORUBA

OSE KESAN-AN

AKORI EKO: ATUNYEWO APEJUWE IRO KONSONANTI ATI IRO FAWELI

Iro konsonanti ni awon iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi n gbe won jade.

Idiwo le waye nipa ki ona eemi se patapata, ki iro jade pelu ariwo taki ki o se die ki iro jade
ni irorun. Awon iro konsonanti ede Yoruba ni:

d, b, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y.

ABUDA IRO KONSONANTI: Ti a ba fe se apejuwe iro konsonanti nipa abuda, a nilati wo awon
ilana wonyi wo ni okookan:

(i) Orison eemi ti a fi n pe iro


(ii) Irufe eemi ti a lo
(iii) Ipo alafo tan-an-na
(iv) Ipo afase
(v) Irufe afipe ti a lo
(vi) Irufe idiwo ti o wa fun eemi

Orisun eemi ti a fi pe iro: A nilati so orison eemi ti a lo lati pe iro konsonanti, yala

- Eemi edo-foro lati inu edo-foro ni tabi


- Eemi amisinu ti a seda re wa ni enu

Eemi edo-foro ni a fi n gbe gbogbo konsonanti ayafi iro /kp/ ati /gb/ ti a n lo apapo eemi
edo-foro ati eemi ti a seda re wa ni enu.

Irufe eemi ti a fi gbe iro jade: A nilati so iru eemi ti a fi gbe iro konsonanti jade: Yala

- Eemi amisode;
- Eemi amisinu; tabi
- Apapo eemi mejeeji (bi o se ri ti a ba pe iro /kp/ ati /gb/)

Ipo alafo tan-an-na: A nilati so ipo tan-an-na ofun wa boya

- Ipo imi (fun iro aikunyun) tabi


- Ipo ikun (fun iro akunyun)

Ipo ti afase wa: A nilati so boya

- Afase gbera soke di kaa imu ni tabi


- Afase wale fun eemi lati gba kaa enu ati imu jade leekan naa.

Irufe afipe ti a lo: A nilati fi han boya

- Afipe asunsi ni a n lo tabi


- Afipe akanmole
- Ipa ti afipe kookan ko nogba ti a ba pe iro konsonanti.

Irufe idiwo to wa fun eemi ti a lo: A gbodo so irufe idiwo ti o sele si eemi ni opona
ajemohun, boya

- Ona se patapata ni; tabi


- Alafo die si sile fun eemi lati koja

A le wa se apejuwe abuda iro konsonanti ni okookan bayii. Bi apeere: iro /b/:

(i) Orison eemi - eemi edo-foro ni a lo


(ii) Irufe eemi - eemi amisode
(iii) Ipo alafo tan-an-na - alafo tan-an-na wan i ipo ikun
(iv) Ipo afase - afase gbera soke di ona si imu
(v) Irufe afipe - ete isale (asunsi) pade ete oke (akanmole)
(vi) Iru idiwo - ona eemi se patapata ni sakani ete mejeeji

ATE KONSONANTI

Ate yii fi gbogbo alaye wa lori owoo konsonanti han ni soki.

Ona Isenupe Afeji Afey Aferi Afaja- Afajap Afaf Afitan Afafa
-ete- in- -gipe fe- e asep -an- -
pe fete- rigi-pe e nape sefet
pe e-pe
Asenupe Akunyun b d g gb
Aikunyin t k p
Aseesetan Akunyun y w
Asesi Akunyun j
Afunnupe Aikunyun f s ṣ h
Afegbe-enu-pe Akunyun l
Aranmupe Akunyun m n
Arehon Akunyun r
DIDARUKO IRO KONSONANTI

A le se apejuwe iro konsonanti bayii:

[b] Konsonanti akunyun afeji-ete-pe asenupe


[d] konsonanti akunyun aferigipe asenupe
[g] Konsonanti akunyun afafasepe asenupe
[gb] Konsonanti akunyun afafasefetepe asenupe
[f] Konsoanti aikunyun afeyinfete afunnupe
[h] Konsonanti aikunyun afitan-an-nape afunnupe
[dz] Konsonanti akunyun afajaferigipe asesi
[k] Konsonanti aikunyun afafasepe asenupe
[l] Konsonanti akunyun aferigipe afegbe-enu-pe
[m] Konsonanti akunyun afeji-ete-pe aranmu
[n] Konsonanti akunyun aferigipe aranmu
[kp] Konsonanti aikunyun afafasefetepe asenupe
[r] Konsonanti akunyun aferigipe arehon
[s] Konsonanti aikunyun aferigipe afunnupe
[ʃ] Konsonanti aikunyun afajaferigipe afunnupe
[t] Konsonanti aikunyun aferigipe asenupe
[w] Konsonanti akunyun afafasefetepe aseesetan
[j] Konsonanti akunyun afajape aseesetan.

IRO FAWELI: Faweli ni awon iro ti a pe jade nigba ti ko si idiwo Kankan fun eemi to n ti inu
edo-foro bo.

Iro faweli ede Yoruba pin si orisii meji. Awon ni:

(i) Faweli airanmupe: a, e, ҿ, i, o, ϙ, u


(ii) Faweli aranmupe: an, ҿn, in, ϙn, un

Lati se apejuwe abuda iro faweli ede Yoruca, a nilati ye ipo ti awon eya ara ifo meta wonyi
wa wo:

(i) ahon
(ii) afase, ati
(iii) ete

Ipo ti ahon wa: A gbodo se akiyesi

(a) apa kan ara ahon to gbe soke julo ninu enu (boya iwaju, aarin tabi eyin ahon)
(b) bi apa kan to gbe soke naa se ga to ni enu. Bi apeere, bi a ba pe iro /i/:
(i) iwaju ahon lo gbe soke jule ni enu
(ii) giga iwaju ahon feree de oke tente ni enu

ATE FAWELI: Ate isaje yii ni so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba gbe iro faweli kookan jade.

Faweli airanmupe

Didaruko Faweli:

A le fun awon iro faweli kookan ni oruko bayii:


[a] faweli airanmupe ayanupe (odo) aarin perese
[e] faweli airanmupe ahanudiepe (ebake) iwaju perese
[ε] faweli airanmupe ayanudiepe (ebado) iwaju perese
[i] faweli airanmupe ahanupe (oke) iwaju perese
[o] faweli airanmupe ahanudiepe (ebake) eyin roboto
[ᴝ] faweli airanmupe ayanudiepe (ebado) eyin roboto
[u] faweli airanmupe ahanupe (oke) eyin roboto

FAWELI ARANMUPE

Didaruko Faweli: A le fun awon iro faweli kookan ni oruko bayii:


[ā] faweli aranmupe ayanupe aarin perese

[ε] faweli aranmupe ayanudiepe iwaju perese

[i] faweli aranmupe ahanupe iwaju perese

[ᴝ] faweli aranmupe ayanudiepe eyin roboto

[ṻ] faweli aranmupe ahanupe eyin roboto

AKORI EKO: ERO ATI IGBAGBO YORUBA LORI AKUDAAYA ATI ABAMI EDA

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYINWAYE

Awon Yoruba ni igbagbo ti o jinle ninu aseyinwaye (iyen leyin iku) igbagbo ninu pipada
wasiaye eni to ti ku yii wa ni aye atijo bee ni o si wa titi di oni.

Ni ona kinni, nibi isinku agba fi ese igbagbo yii mule. Ey ribee nigba ti agbalagba kan ninu
idile ba ku (yala okunrin tabi obinrin) ti iyawo omo re ba wa ninu oyun ni akoko naa ti
omobinrin naa ba ti mo okunrin tabi obinrin leyin iku baba tabi iya agba oruko ti won yoo so
iru omo bee ni (ti o ba je okunrin) Babatunde, Babajide, abbl. Sugbon ti o ba je omobinrin,
oruko ti won yoo ma pee ni Yetunde, Yeside, Iyabo, Yewande, Yejide abbl.

Ona keji ewe awon Yoruba tun gbagbo pe ti enikan ba ku nigba ti ojo re ni aye ko tii pe lati
ku kii lo si orun taara, se ni won yoo wa ibikan tedo si tabi ki won maa rare kiri titi ojo re yoo
fipe ni aye ki o to le pada lo si orun. Iru awon ti won ba fi ojo dajo lo bayii ni a n pen i
akudaaya tabi akufon

Ona keta igbagbo awon Yoruba nipa abiku fi idi iye leyin iku mule. Abiku ni omo ti o ku, ti o
tun pada wa si aye, o tun le ku, ki o si tun pada waye ni igba ti o ba wuu. Atigbo nipa abiku ti
won ge ika owo re ti o si jepe igbati obinrin to bii ya pada bi omo, ika owo mesan-an ni omo
tuntun ti o bi gbe waye. Eyi fihan pe omo akoko iru omo bee ni; Kokumo, Igbekoyi, Malomo,
Bamitale, Durorike, Kosoko abbl.

Ona kerin, awon Yoruba tun gbagbo pe awon iwin ati egbere wa, atipe eniyan ni won tele ki
won to di ebora. D.O. Faganwa fi igbagbo yii han ninu awon iwe itan aroso. Oro eda inu itan
iwe re je oro tabi iwin. Inu igi bii igi iroko, igi agbalumo, inu igi ibepe, igi ahusa, agbo ogede
ni won ngbe. Won asi maa yipada si eniyan nigba ti o ba wu won. Awon Yoruba tile gba pe
won maa n na oja ale. Bakannaa ni awon ogboju ode maa n royin itu ti awon ebora maa n fi
won pa ninu igbnigba ti won ba n sode ninu igbo.

Ona karun-un, awon Yoruba tun gbagbo pe awon elegbe omo wa. Awon omo elegbe bi eyi
maa n yo obi won lenu. Aimoye won ni won maa n lo agbara won lati se obi won ni ibi. Ipese
ni won maa n se fun won lati tu won loju. Won ti e maa n ka eewo fun awon obi won ti won
ko gbodo lana lati se bii beeko, won yoo yo iya won lenu.

Won tun gbagbo wipe awon eyan to n wo aso egungun o se eniyan lasan pe awon alagbara
eyan niwon tabi ole.

You might also like