You are on page 1of 2

Deeti: 24th May 2021

Eka Eko: jss2

Ise: Yoruba

Akole: Asa iranraenilowo nile Yoruba

Awon Yoruba bo, won ni, Bi ojojo ba n se okan ore, gbogbo wa ni ojojo jo n se. Itumo adamo owe yii nip
e bi aisan ba n se ore eni kan, bi a ko ba tete ba a moju to o, aisan naa le ran ore to sunmo o. Ni aye
atijo, awon Yoruba kii foju kere ajosepo idi niyi ti won fi ma n pa owe naa wipe ‘ Ajeji owo kan ko gberu
dori.

Awon Yoruba ni ona iranraenilowo lorisirisi lara won ni;

1. Arokodoko: je asa iranra enilowo ti o ma n waye laarin eniyan meji tabi meta ti oko won ba
fegbekegbe. Awon odomokunrin bii meji tabi meta fi n sowopo ba ara won sise oko. Awon to ba
je iro, ti won je ore ti oko won ko sit un jinna si ara won lo maa n ba ara won sise bayii. Bi won
ba je meji, awon mejeeji yoo lo si oko eni kan lati sise lonii. Bi o ba di ojo keji, oko enikeji ni won
yoo lo.
2. Aaro: Laye atijo, awon odomokunrin ti o je iro kan naa a maa sowopo sise ninu oko ara won.
Awon bee a maa je awon ti oko won ko fi bee jinna si ara won. Awon bee a maa je awon ti oko
won ko jinna si ara won. Awon wonyi le je okunrin tabi obinrin. Awon ti won ban i agbara bakan
n aa ni won maa n da aaro nitori pe eyi ko fi aye gba iwa ole. Won yoo maa se eyi lati odo eni
kan titi yoo fi kari gbogbo elegbe aaro.
3. Oya: Ko si iyato laarin aro ati oya. Awon Ekiti lo n fi oya ran ara won lowo ninu ise oko won.
Iyato die kinun to wa laarin aaro ati oya nipe ofin oya le ju aaro lo. Bi won ko ba pari ise ti won
fi enu ko si lati se, won ko ni siwo bot i wu ki ile su to. Koda ti ojo ba n ro ina, ko gbodo si awawi
fun eni kan pe ojo ni ko je ki oun wa sise ninu oko eni ti oya kan.
4. Owe: Ise ti o po jaburata ti eniyan ko le da se funrare bi o ti wu ki o lagbara to ni won n fi owe se.
Laye atijo, a ri eni ti o fi owe se ipile ile, ti o fi owe mo gbogbo ile. Awon Yoruba ma n ye ana si
pupo. Ana eni le be oko omo re lati baa sise ninu oko lati ibere titi de opin. A le be ogorun un
eniyan lowe.
5. Ebese: Ebese ni ise ti ko fi bee po ti a be awon eniyan lati se fun ni paapaa fun igbaradi fun
inawo repete ti n bo niwaju. Bi apeere bi eni kan ba fe gbeyawo, O le be awon ore re ni igi se
tabi ina dida.

Akole: Asa iranra enilowo laye atijo ati lode oni

Lara ohun ti a fin ran ara eni lowi laye atijo ati lode oni ni:

1. Esusu/ Eesu: Esusu je ona Pataki ti awon Yoruba fi n ran ara won lowo laye atijo ati lode oni. Esusu dida ni
awon eto ati ilana ti a n tele. Lakoko, awon to mo ara won deledele, ti won je olotito eniyan lo n ko ara won
jo lati da esusu. Lona keji, won gbodo se adehun iye ti eni kookan yoo maa da gege bi agbara re bati to. Eyi ni
pe eni kan le maa da naira marun ki eni keji da naira mewaa. Se agbara gbogbo eniyan ko kuku dogba. Won
yoo yan olori laarin ara won. Eni ti won bay an gege bi olori ni a n pen i olori eleesu ni apa ibikan. Sugbon laye
ode oni esusu olojoojumo, olosoose ati olosoosu lo wopo julo.
2. Ajo: Ajo je ona miran ti a n gba fi ran ara eni lowo. A ma n da ajo bi igba ti a n da esusu naa ni. Iye ti eniyan
ban i agbara nii da gege bi esusu. Adehun a maa wa laarin awon to n da ajo lati mo igba ti won yoo da a da, ki
o to pari ati bi won yoo se maa ko o. Nigba miran won yoo da ajo si odo olori alajo titi di igba ti won yoo pejo
lati pin ajo ti onikaluku da. Lode oni ajo ojoojumo lo po ju, osoosu sin i alajo. Iyato die wa laarin ajo ati esusu.
Iye esusu ti eniyan ba da ni yoo ko gereege, ko ni din bee ni ko si nile. Sugbon eniyan ko le ko gbogbo ajo to n
da tan, oluware yoo se eyo kan ku. Olori alajo lo ni eyo kan to ba ku.
3. Oja awin tabi aradosu: Ona iranlowo miran ni oja awin tabi aradosu je, o sit i wa tipe. Bi eniyan ba f era
ohun kan, ti nnkan naa si je oran-an-yan lati ni, ohun ti o le se ni lati lo ya owo ra a. Sugbon ti ko bar i owo ya,
Ohun to tun le se nip e ki o to eni to n ta a lo boya oluware le taa fun un lawin lori adehun pe oun yoo maa
san owo re diedie. Bi oloja bee ba ta nnkan naa fun un, Iranlowo nla ni a se fun un. Awon ijesha ni okiki nipa
iru eyi. Won yoo ta oja aradosu fun eniyan lori adehun pea won n bow a gba owo ni ipari osu tabi ni igba ti
won dijo fi adehun si. Irorun ti de ba ilana yii lode-oni nitori pe irufe adehun yii laarin awon ontaja ti n ni owo
awon amofin ninu, ikeji ni san-die- die. Itumo re ni pe yoo maa san owo oja die die titi yoo fi san tan.
4. Owo ele kiko: Bi okun owo ba mu elomiran, won a maa lo sodo awon to n gba owo lori owo ti won ya
oluware. Ele ori owo bee a maa po to bee ti kii fi I irorun lati san iru owo bee pada fun igba pipe. Iranlowo ni
owo-ele kiko ma n je asiko ti eni ti o yaa ba lo yaa. Sugbon igbeyin re kii dara paapaa fun eni to yaa ati fun eni
ti o fi ya ni.
5. Egbe alafowosowopo ode oni: ni a tun n dape ni alajeseku je egbe ti a ko jo nitori a ti maa ran ara eni
lowo. Iru egbe yii wa kaakiri lawujo wa. O wani ile ise oba, o wa laarin awon iyaloja ati awon onise adani,
awon oloko-owo keekeke abbl. Ofin wa ti o n dari egbe alafowosowopo. Egbe kookan gbodo ni ile iya egbe,
won si gbodo foruko sile lodo ijoba. Iwe eri si wa fun egbe ti o ba fi oruko sile. Awon anfaani to wa nibe ni
wipe a le toju owo sibe. Iru owo ti a ba toju sibe kii din, o si ma n le sin i. Eniyan si le ya owo nibe, bi bukaata
kan ba de ba eniyan. Alafowosowopo ma n bo asiri gidi ni. Eniyan le ya ilopo meji tabi meta owo ti o ni ninu
egbe. Ele ti o ma san ko nip o rara. Eniyan le ya owo tabi gba ohun jije nibe,ti yoo si maa san owo re diedie.

You might also like