You are on page 1of 2

ETO IGBEYAWO MIMO NI CELESTIAL CHURCH OF CHRIST

1. IGBEYAWO BERE
Gbogbo ijo Oluwa yoo joko. Fifa Iyawo le Baba ati Iya Oko lowo. Gba owo Baba ati
Iya iyawo pelu awon oro wonyi. “Gegebi ife ti ari laarin omo yin si omo wa ati gege
bi itoro ati idana ti a se lori omo wa, a nfi omo wa ……(oruko) le yin lowo ni Iyawo
fun omo yin pelu idaniloju ibunkun lati odo Olorun lori won (Amin.)
Baba ati Iya Oko yoo gba iyawo pelu oro ope lenu Baba ati Iya oko “Adupe fun ife ti
e ni si wa lati fi omo yin fun wa ni aya fun omo wa…… (oruko).
Awa pelu ni idaniloju ibukun lati odo Olorun lori won (Amin.)”
Nisisiyi, Baba ati Iya Oko yoo wa fi Oko ati Iyawo le awon alagba ijo lowo (Okunrin
1, Obinrin 1) pelu oro wonyi.
Eyin alagba ninu Oluwa, a fi oko ati iyawo yii le yin lowo fun itoju ati ifimona kuro
ninu idanwo aye ati fun idapo ododo laarin awon mejeeji ninu ife aisetan ati isinmi
okan pipe lojo aye won. Ki Oluwa ki o ranyi lowo (Amin)
Awon alagba Ijo yii yoo wa fa Oko ati Iyawo le asiwaju esin lowo (Officiating
Ministers).
Oro lenu awon alagba ijo si asiwaju esin:
“Alagba wa, a fa awon tokotaya yii leyin lowo, fun esin ibukun niwaju Oluwa.”
Nisisiyi, Asiwaju esin yoo wa mu Iyawo lowo koju si gbogbo ijo pelu oro wonyi
dapo mo Oko re loni.
Nje ari enikan ti o ni atako si igbeyawo yi bi! Ti o ba wa, a o bere oro yi ni igba meta.
Ti ko ba si atako kankan, nje awon mejeeji di alase ati ominira si ara won laikosi
ikose ati idalowoko lati odo eniyan. Ki Oluwa ki o ran won lowo (Amin).
Oko Iyawo yoo wa fi owo otun re di osi Iyawo re mu ni kikoju si Ijo Oluwa, yoo maa
wi tele asiwaju esin baayi pe:
“Emi ………… (Oruko) gba iwo …………. (oruko Iyawo) ni Aya mi lati fee, lati
kee titi iku yoo fi yawa, gege bii idasile mimo Olorun si eyi, mo fi otito mi fun o”.
Iyawo naa yoo fi owo otun re gba oko re mu, yoo wi tele Asiwaju esin baayi wipe:
“Emi ………… (Oruko) gba iwo …………. (oruko Oko iyawo) ni Oko mi lati ni,
ati lati muu, lati fee ati lati kee titi iku yoo fi yawa, gege bii idasile mimo Olorun si
eyi, mo fi otito mi fun o”.
ORUKA (meji) ti won ti mu wa siwaju pepe fun iya si mimo.
Nigbanaa ni Oko iyawo yoo fi oruka si Iyawo re ni ika kerin owo osi. Yoo di oruka
naa mu, yoo wi tele asiwaju esin bayii wipe:
“Oruka yi ni mo fi ba o gbe iyawo, ara mi ni emi yoo fi maa bu ola fun o ati ohun
ini mi gbogbo ni emi yoo fi maa ke o ni oruko Jesu Kristi Oluwa wa (Amin).
Iyawo naa yoo se bee gege yoo si so oro kan naa fun oko re. Bi won se nse eto wonyi,
Ore Oko ati Ore Iyawo yoo duro leyin oko iyawo ati iyawo. Ni akoko yii naa won yoo
koju si pepe Oluwa.
Leyin eyi, Oko ati Iyawo yoo fi owo ko ara won lati lo si ori ijoko won tuntun.
2. EKO KIKA, GLORIA
3. IFILO, IJEWO IGBAGBO
4. IWAASU
5. ADURA KUKURU LEHIN OUNJE EMI
6. OWO IGBA
7. GBIGBA ARA OLUWA ( Pelu orin Mo nbe ninu ododo) (Emi mimo sokale saarin
wa)
Gbigba ara Oluwa yoo lo ni telentele baayi
 Alagba asiwaju esin ati alagba to ba tun ye.
 Oko ati Iyawo.
 Iya Oko, Baba Oko, Iya Iyawo ati Baba Iyawo.
 Agba Ijo okunrin ati obinrin
 Awon afenifere.
8. OPE
9. OKO ATI IYAWO YOO TOWO BO IWE ERI IGBEYAWO.

You might also like